OJUONA ORIIRE

OJUONA ORIIRE

OJUONA ORIIRE

طريق السعادة بلغة اليوروبا

 

 

 

‘Abd Ar-Rahmân bin ‘Abd Al-Karîm Ash-Sheha

د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 

 

 

Itumo ni ede Yoruba

EUROPEAN ISLAMIC RESEARCH CENTER (EIRC)

المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية

& Abd Ar-Razzaq Isa

Atunto

Ridwanu Allah Murtadho

 

WWW.ISLAMLAND.COM

 

 

 

 

NI ORUKO OLOHUN, AR-RAHMAN (OBA AJOKE AYE), AR-RAHEEM (ASAKE ORUN)

 

ITISIWAJU

Gbogbo ope n je ti Olohun, Ike ati Ola Olohun fun Anabi wa Muhammad ati fun awon ara ile re, ati fun awon (sahabe) ti won ba lo igba ti won si ni igbagbo si Olohun. Leyin naa: Awon iseju die ti o maa lo fun ati ka tira kekere yii, yio sokunfa oriire gbere fun o, nipa bayi ma kanju lati mu idajo ofin wa, ma si kanju nibi kika tira yii, tori pe kika aarin tira pelu ikanju lai ronu si ohun ti a ka, ko tumo si pe a ti ka a.

Ibere: Ile aye ti a n gbe yii je ile aye ti o rewa ti o si leto si ki a ronu si i, tori pe awon eda Olohun inu re n safihan imole ati ironu ti a o so pe o ba opolo mu fun awon onilaakaye nipa didaju bibe Adeda ti o da a ni dida to rewa pupo, Iye maa n je sise latari ironu si siso awon abala nnkankan po mo ara won dogba lo je yala o je awon agbaye eyi ti a le foju ri (awon eda inu re) ti o si ga ju, eyi ti o ko awon irawo ti o tobi sinu, tabi o je awon agbaye eyi ti a ko le tete foju ri awon eda inu re fun wipe won kere ni irisi, awon eda bii oka baba ati awon eya re. nitori pe ti ko ba si agbara Adeda, Apebubu nnkan, Oluso Alaabo to nipon fun awon eda, gbogbo eda ni yoo ti wo subu, gbogbo won si ni yoo maa kolu ara won, sugbon gbogbo nnkan kookan n rin ni opopona re, ti o si n se regi, ti o si n lo letoleto, gegebi Olohun ti Ola Re ga ti salaye eyi pelu gbolohun Re yii:

"لاَ الشَّمْسُ يَنبَغِي لَهَا أَن تُدْرِكَ الْقَمَرَ وَلاَ اللَّيْلُ سَابِقُ النَّهَارِ وَكُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ " (سورة يس 40)

“Ko to fun oorun lati lo asiko Osupa, ko si to fun ale lati lo asiko osan. Ikookan wa ni opopona ti won nluwe” (Yaasin: 40)

Awon eda to wa ni awon agbaye won yi yio maa lo ni opupona ti e titi ti eni ti o da a yoo fi yonda kikuro ni aye, ninu awon eto ti yio sele ti Olohun ti pebubu re, nitori ki isemi ti torun ti o je isemi gbere le bere:

"إِذَا السَّمَاء انفَطَرَتْ * وَإِذَا الْكَوَاكِبُ انتَثَرَتْ * وَإِذَا الْبِحَارُ فُجِّرَتْ * وَإِذَا الْقُبُورُ بُعْثِرَتْ" (سورة الإنفطار)

“Olohun ti Ola Re ga so pe: Nigba ti Sanmo ba fa ya perepere * Ati nigba ti awon irawo ba jabo kaakiri * Ati nigba ti awon ibudo ba nja papo mora won * Ati nigba ti won ba mu awon Oku jade (laaye) lati inu awon Saree” (Suurah Al – Infitoor: 1 – 4)

Ibeere kan ti o maa sare wa sinu opolo nipa awon agbaye wonyi leyin arojinle ni wipe kinni ogbon ti o wa ninu dida gbogbo awon nnkan wonyii: Nje won dawon fun titori ere lasan laini anfaani Kankan nibi? Ninu awon eda ti o wa ninu agbaye si ni eniyan eleyi ti papaa dida re seniyan leemo, ti tito papo orikerike ti o han jade nibi eda re, si ya eniyan lenu pleu. Tori idi eyi, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الإِنسَانُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ الْكَرِيمِ * الَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّاكَ فَعَدَلَكَ * فِي أَيِّ صُورَةٍ مَّا شَاء رَكَّبَكَ* " (سورة الإنفطار 6-8)

“Iwo eniyan, ki ni o tan o je nipa Oluwa re, Alaponle? * Eni ti o da o, o se (eda) re ni pipe perepere. O si mu o dogba jale leeyan* O to (eya ara) re papo sinu eyikeyi ti O fe*” (Suurah al – Infitoor 6 – 8)

Bakanna, ti tito papo orikerike ti o pamo nibi eda re naa tun ya eniyan lenu. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَفِي أَنفُسِكُمْ أَفَلاَ تُبْصِرُونَ " (سورة الذاريات 21)

“Ninu ara yin gan – an (ami wa ninu re) se eyin ko riran ni?” (Dhaariyaat: 21)

Ninu awon nnkan ti o yeni, ti a si mo daradara ni pe, nibi gbogbo oro ile aye omoniyan, eniyan koole se nnkankan ayafi nnkan ti yoo biya bukata re tabi ti yio mu anfaani kan wa leyin ti o ba se tan. Tolohun ni apejuwe ti o dara ju. Olohun ti Ola Re ga tobi pupo tayo ki o wada nnkan fun ere lasan. Idi niyi ti Olohun (ti mimo je ti E) sope:

" أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ (115) فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ (116) " (سورة المؤمنون:115-116)

“Se e lero pe A kan da yin fun iranu ni, ati pe eyin konii pada si odo wa? Giga fun Olohun, Oba paapa, kosi olohun miran ayafi oun na, Oluwa aga (al arashi) aga aponle” (Al – Muminuun:115-116)

Ile aye yi pelu awon irawo (falak) awon irawo (kaokab), ati awon irawo (Najmu) ti o wa nibe, ati awon Sanmo, ati ile naa ti o wa nibe, Olohun ti Ola Re ga dawon fun a ti le, ronu ni arojinle ni ironu ti yoo fa ibeere wi pe taani o da gbogbo awon nnkan wonyii? Eleyi yoo sita opolo ti o ni Alafia ji, ati opolo ti o lagbara a ti le da nnkan mo ji, sibi dida Olohun Eleda mo daradara (Mimo fun Olohun ti Ola Re ga) Olohun ti Ola Re ga so pe:  

"الَّذِينَ يَذْكُرُونَ اللّهَ قِيَامًا وَقُعُودًا وَعَلَىَ جُنُوبِهِمْ وَيَتَفَكَّرُونَ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ رَبَّنَا مَا خَلَقْتَ هَذا بَاطِلاً سُبْحَانَكَ فَقِنَا عَذَابَ النَّارِ "{آل عمران/191}

“Awon ti n ranti Olohun ni inaro, ijokoo ati ni idubule, won n ronu si iseda awon Sanmo ati ile, (won si n so pe) “Oluwa wa, Iwo ko sedaa eyi fun iranu. Mimo ni fun O. nitori naa, so wa nibi iya ina.” (Al – Imroon 191)

Eni ti o so agbaye yi di bibe lati ibi aisi yio sodi titan ki isemi gbere le bere, Olohun ti ola Re ga sope:

"يَوْمَ نَطْوِي السَّمَاء كَطَيِّ السِّجِلِّ لِلْكُتُبِ كَمَا بَدَأْنَا أَوَّلَ خَلْقٍ نُّعِيدُهُ وَعْدًا عَلَيْنَا إِنَّا كُنَّا فَاعِلِينَ" (الأنبياء/104)

“(Ojo naa ni) Ojo ti A maa ka Sanmo bii kika ewe tira. Gege bi A ti se bere iseda eda ni ibere pepe (Ibe naa ni) A oo da a pada si. (O je) adehun ti A se. Dajudaju Awa yoo se bee” (Al – Anbyaa: 104).

Iwo naa ti o je eniyan o je okan lara ohun ti aye yi ko sinu, iru titan ti yio de ba aye yio de ba iwo naa pelu, sugbon iyato ti o wa nibe ni pe, won yoo gbe iwo dide pada lati semi fun igba miiran, won yoo si se isiro ise re fun o, won yoo si fi Alujanna tabi Ina san esan fun o. nipa bayi eni ti O mu o maa semi nigba akoko ni agbara lati je ki o tun maa be ni abemi leyin iku, o si lagbara lati gbe o dide leyin iku, eleyi je ohun ti o rorun fun – un (lati se bee).

" وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَى فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ " )الروم:27(

“Oun ni o bere dida eda, yoo si da pada, osi rorun fun, osi ni apejuwe ti o ga julo ni sanmo ati ni ile, oun si ni Oba-nla, ojogbon” (Suurah ar-Ruum: 28)

Woye si awon ile Okoo gbigbe ti o ti ku debi wi pe kosi irugbin kan tabi omi nibe ti o pada di ohun ti Ojo ro si i, ti o pada di ohun ti o ropo mo erupe, ti osi pada di petepete, ti o si tun pada di ohun ti kosi ilapa wi pe o ti fi igba kan semi ri leyin awon Ojo ati Osu melo kan. Sugbon nigba ti Ojo ro si I, o pada di ile Olora ti awon orisirisi irugbiin si n jade nibe. Eleyi maa je kodi mimo fun o wi pe igbende leyin iku, eleyi ti o n ru opolo loju, je ohun ti o rorun fun Olohun lati se bee. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمِنْ آيَاتِهِ أَنَّكَ تَرَى الأَرْضَ خَاشِعَةً فَإِذَا أَنزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاء اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ إِنَّ الَّذِي أَحْيَاهَا لَمُحْيِي الْمَوْتَى إِنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ "{فصلت/39}

“Ninu awon ami Re tun ni pe dajudaju iwo yoo ri ile ni asale. Nigba ti A ba si so omi kale le e lori, o maa rura wa, o si maa yanu (fun hihu irugbin jade)/. Dajudaju Eni ti O ji I, Oun na ni Eni ti o maa so awon oku di alaaye. Dajudaju Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan” (Fussilat: 39)

 

 

 

‘Abd Ar-Rahmân bin ‘Abd Al-Karîm Ash-Sheha

/Users/ahmed/Documents/MY SITES & PROJECTS/PROJECTS & SITES/ISLAMLAND/logo-black.png

WWW.ISLAMLAND.COM

[email protected]

 

 

ORIIRE

Nje o mo itumo oriire bi? Oriire, ni igbanmo ayo ati idunu ninu ara yato si idunnu eyi ti o han ni ita, ti o si maa n je ohun ti a mo pa lori yiyonu si ise, ati lori igbagbo ti a ni lokan. Gbogbo eniyan ni o se dandan fun lati ni afojusun ti yoo maa se ise to amuse re. deede bi o ba se sapa to fun amuse re naa si ni yoo ni igbanmo oriire to.

Awon onimimo nipa emi ati nipa rire omo maa n ki oriire bayi. “Oriire ni didamo ayo ifokanbale, itura, itutuoju ti o n sele ti ko duro, ti awon didamo ohun ti o maa n fa oriire wonyi si maa n waye latari ifuramo Oore paapaa, Oore isemi ati ayipada Oloore yio maa wa eniyan.”

Iwo naa o ti le ko emi re ni oriki ti o ye fun oriire lati inu agboye ninu oriki ti a mu wa fun oriire bayii.

 

AWON ORISIRISI IPIN ORIIRE

Oriire Akoko: Eleyi ni oriire eyi ti a maa n ro lokan ti kosi ri bee, ti o si maa n ni gbedeke asiko. oun ni dida oriire mo gegebi abajade ise ti o han, opolopo awon eniyan ni o maa n lero pe oriire ni lilo awon nkan ti muni hunrira ati oti, awon wonyi won o mojuto awon nkan wonyi lati le sa kuro fun awon ibanuje ati awon isoro aye fun awon adisokan won wi pe oriire n be ninu gbigbagbe awon isele kan ti o n sele ti ko fi igba kan duro, sugbon awon ti o ni irori yi ri ara won gegebi eni ti o n wa imoribo ninu Ooru ina ti o le koko beesi ni won o le ri abajade kan kan nibi eleyi bi ko se ori buruku, Idi ni pe awon idunnu ti o pamo maa n sokunfa oriire ti o nipon sugbon ti o le dopin tabi ki o pari pelu pipari ohun ti o sokunfa re, Bee si tun ni oro maa n nipon pelu a i si oriire fun nitori aisi ohun ti o le sokunfa oriire naa. Iye ri bee tori ki o le di ebun oore fun awon oore ti o pamo tiit ti oriire ti o po ju bi a se lero lo yio se waye, ti iru eni yi maa fi waa ri ara re ni eru fun awon oun ti o pamo, laini agbara a ti le gbejusile fun wi pe o le fa awon aisan emi ti o lagbara ju oore ebun ti o le mu wa lo, ni tori igbagbe re ti eniyan le gbagbe maa di afikun si awon aisan ara, beesi ni eleyi maa gbe lo sibi ese sise.

Oriire elekeji: Eleyi ni oriire amuse awon afojusun, ohun ni oriire kan to sopo mo amuse awon afojusun eleyi ti o je eyi ti a se oju oyin si tabi afojusun eleyi ti a n wa. Iru oriire bayi naa dabi eyi ti a so siwaju nibi abala yiye kuro oriire leyin ifidimule afojusun sugbon inira ti e kere si takoko fun bi o se je pe o ni ilapa ti o jeyo sita ti o si tun farapamo de ibi pe o le fa awon aisan temi tabi ti tara. Leyin ibeere ti o ko idaamu ba opolopo eniyan yi o bere leyin ti awon afojusun ti di mimu se," leyinnaa kin tun ni?" Ibeere yi ni ibere idaamu ti o ba emi!

Oriire eleketa: Oriire ni ti paapaa, ni oriire gbere, ohun ni oriire ti o maa n be pelu omoniyan nigba gbogbo awon isesi re yala nibi isesi iyonu, ati ibinu, isesi ninu alaaafia ati aisan, isesi oro ati osi, isesi ki omoniyan ri gbogbo ohun ti o n wa ni ile aye yi tabi ko ri i. eleyi ni oriire ni ti tooto, eleyi ti o maa n fa idunnu ni igbagbo, ti o si tun je eyi ti a mo pa lori igbagbo ti o fi di mule ti o si maa n fa ifokanbale okan ati ifokanbale emi

 

 

 

NJE O NIFE SI ORIIRE PAAPA (ORIIRE TOOTO)?

O le je pe ibeere yi se ajoji, Idahun si je ohun ti a ti mo ki a to so. O rewa pupo ki n se iwadi ati ise to dahun si i. sugbon gbogbo nnkan loni ogbon ti a fi maa n se e, oni bi a ti le ri oriire yii. Ona ti o le fa a wa, nbe ninu awon eniyan eni ti o ri oriire si kikojo owo ati oro. Nbe ninu won eniti o ri i pe ibi ki a ni opolopo ore ati agbara a ti o le gbe Ola fun nnkankan ju nnkan miiran lo. Sugbon ti o ba beere lowo gbogbo eni ti o ri amuse erongba re, ti o si ri awon nnkan ti o n wa ninu dukia ojulowo taabi dukia ti ki i se ojulowo, ti o waa beere lowo irufe eni ti o ti ri amuse erongba re, wi pe: Nje o ti ri oriire ogidi. Nnkan ti iru eni yi o so ni “Rara”! Sugbon ibeere ni pe, kinni o fa ti ko fi ri ogidi oriire? Maa bi o pe kinni o fa. Tori pe ogidi oriire wa nibi bibale emi ati isinmi okan ni gbogbo igba, gbogbo awon ohun ti a so soke ko le maa be fun eniyan, koda ki o se pe eniyan ni goolu ti o gba gbogbo ori ile aye ni dukia, ayafi ki o ri i, nipa ki o ni awon nnkan ti o le sokunfa ki eniyan ni i, a si n bowa soro nipa awon nnkan ti o le sokunfa ki eniyn ri awon ohun ti a so soke yi.

Fun apeere: O le lagbara lati ra ibusun sugbon o ko le ni agbara lati ra oorun!! Nje gbogbo nnkan ti dopin bi? Eleyi ti ye wipe gbogbo eniyan kookan lo ni ohun ti o n fe ati afoju sun re nibi kiko owo jo, ati dide ipo, ati iyi ati lilo agbara? Leyin naa kin tun ni? Ibeere yi ni o maa so gbogbo eniyan kookan di eni ti ko ni le se esin tabi ki o soo di eni ti koni le maa se akolekan esin re. iye maa ri bee fun nitori awon nnkan ti o wa ninu re ti o tako imo ti o ni alaafia, yio si mu ki eniyan lo isemi ti kii se isemi oloriire, tori pe eni ti o ba lero pe gbogbo nnkan ti dopin, awon nnkan ti o maa n fa oriire eleyi ti a maa n ro yoo wa seri ba a gege bi a ti so soke, gegebi awon ohun ti o maa n pani bi oti, ti eniyan o fi waa gbagbe ohun ti o le gbe ni de ipo oriire eleyi ti a nroyin, ati ifokanbale ti o kun, sugbon oriire ati ifokanbale iru eyi je ohun ti o ni asiko, eyi si maa n dopin pelu didopin awon nnkan ti o n fa a. bii awon nnkan ti o maa n pa ni bi oti, ti yio si so di olugbiyanju nibi i maa ri ore gba leekan si, lati le gbagbe wi pe adamo yi so mo sise afeku oriire, kosi ohun ti ole di aye airi oriire ayafi ini akakun esin eyi ti a maa se amulo latari akolekan esin ti o ni alaafia, taa si fi n mo enu aala bi esin se so.

Dide ibi ogidi oriire maa rorun fun eni ti Olohun ba se ni irorun fun, o si wa fun gbogbo eniyan lai se iyato iran won, awo won tabi ebi won.

Nje o mo ibi ti o ti le ri Oriire? Ma se je ki eesi ba o lojiji, fun emi re ni aaye lati danwo, bakanna fun ni aaye lati jeran oriire sugbon sise bee yio sele pelu mojemu ki o ni akolekan awon ohun to ye lati ti siwaju, pelu ki o si ni igbagbo ododo si ohun ti o gbagbo, tori pe lopin igba ti omoniyan ba n se iwadi ogidi oriire, o ni lati ni ifarada pelu, ki o fi le ri oriire yii. O si ye ki o fun emi re ni aaye atunse, ki o se ayipada emi re si ohun ti o gbagbo wi pe ohun ni O dara julo, ati fun amuse afojusun ti o n sise to.

Ohun ti o maa nfa oriire fun eniyan ni ki o gba Islam. Mo woye si pe eleyi le ya o lenu!!! Sugbon ohun ti o ko emi ati iwo lorun lori eyi ni ki o je pe o gba Islam pelu majemu pe o gba a lati orison ipile eyi ti o ni alaafia pelu ki o gbe ogbon atinuda ti e sile pelu esin atowoda lati odo ara re. Bakannaa ki o si ni ayookan wi pe latari gbigba Islam re yi lo fi n wa ogidi oriire.

Nje o ti e mo idi ti Islam fi fi ogidi oriire rinle fun o? emi n so fun e pe, kinni idi ti Islam se fi ogidi oriire rinle fun o, a ti so oriki ti awon onimimo nipa emi fun oriire siwaju tele, wi pe: ohun ni owu jije, ifokanbale, Itutuoju, ti a ni ti kosi duro nigba Kankan latari abajade dida awon oore mo, ni gbogbo igba awon oore ni ti papa, oore inu isemi ati oore tinu ibi ti a o pada si. Gbogbo nnkan wonyi si ni Islam fi rinle ninu esin Islam. Lori Oore ni ti paapaa, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ الْمُسْلِمِينَ وَالْمُسْلِمَاتِ وَالْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ وَالْقَانِتِينَ وَالْقَانِتَاتِ وَالصَّادِقِينَ وَالصَّادِقَاتِ وَالصَّابِرِينَ وَالصَّابِرَاتِ وَالْخَاشِعِينَ وَالْخَاشِعَاتِ وَالْمُتَصَدِّقِينَ وَالْمُتَصَدِّقَاتِ وَالصَّائِمِينَ وَالصَّائِمَاتِ وَالْحَافِظِينَ فُرُوجَهُمْ وَالْحَافِظَاتِ وَالذَّاكِرِينَ اللَّهَ كَثِيرًا وَالذَّاكِرَاتِ أَعَدَّ اللَّهُ لَهُم مَّغْفِرَةً وَأَجْرًا عَظِيمًا" (سورة الأحزاب: 33)

“Dajudaju awon musulumi lokunrin ati musulumi lobinrin, awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobirin, awon olutele ase Olohun lokunrin ati awon olutele ase Olohun lobirin, awon olododo lokunrin ati awon olododo lobinrin, awon onisuuru lokunrin ati awon onisuuru lobinrin, awon olupaya Olohun lokunrin ati awon olupaya Olohun lobinrin, awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, awon alaawe lokunrin ati awon alaawe lobinrin, awon ti n so abe won lokunrin ati awon ti n so abe won lobinrin, awon oluranti Olohun ni opolopo lokunriin ati awon oluranti Olohun (ni opolopo) lobinrin; Olohun ti pese aforijin ati esan nla sile de won”. (Suurah Al – Ahzaab:33)

Lori oore tinu Isemi. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"كُنتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَتَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَتُؤْمِنُونَ بِاللّهِ وَلَوْ آمَنَ أَهْلُ الْكِتَابِ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُم مِّنْهُمُ الْمُؤْمِنُونَ وَأَكْثَرُهُمُ الْفَاسِقُونَ" (سورة آل عمران: 110)

“Eyin ni ijo ti o dara ju lo, ti A gbe dide fun awon eniyan; e n pa won ni ase sise daadaa, e n ko sise aidaa, e si ni igbagbo ododo ninu Olohun. Ti o ba je pe awon ti won fun ni tira (ahlu – l – kitaab) gbagbo ni ododo ni, iba dara fun won. Onigbagbo ododo n be ninu won, opolopoo won si ni obileje” (Suurah aali – ‘Imroon: 110)

Lori Oore ti ibi ti a o pada si. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ كَانَتْ لَهُمْ جَنَّاتُ الْفِرْدَوْسِ نُزُلاً* خَالِدِينَ فِيهَا لاَ يَبْغُونَ عَنْهَا حِوَلاً" (سورة الكفهف 107 –108)

“Dajudaju awon ti won gbagbo ni ododo ti won si se awon ise rere, awon ogba Firdaos ti wa fun won ni ibudesi * Olusegbere ni won ninu re. Won ko si ni fe kuro ninu re.” (Suurah al – Kahf 107 – 108)

Nipa bayi, lopin igba ti ogidi oriire ba ti n jeyo pelu yiyonu si ohun ti o maa n fa ifidimule emi ati ifokanbale re nibi awon oore eleketa, eniyan ko ni ti le ni agbara ati le de be, ayafi ki o ni akolekan esin ti awon ohun elo ati emi ti o maa fi se esin yi, yio si gbewon de ibi pe okan koni bori ekeji.

Gbogbo awon eto, ilana ijosin, ati awon orisirisi esin eleyi ti opolopo eniyan n lo lati samulo ti won si n se lesin da gegebi kiko lati lo ofin esin Islam ati gigunri kuro ninu Islam, lati ibere yiyo Islam O si bere sini di ohun ti won wo ipile re lokookan lejeeji, o dabi eni pe igbeyin re ni o fa ifowosowopo (sulviet) (sufiyeti) ijo awon to gbawaju lo, Eto (Rusmalley) (rosimali) ti o wo, eyi ti o ri ara a re bi eyi ti n dari ijoba aye lona ti o fe. Ko le ba a wo bi awon to gbawaju re se ti wo, o ti bere si ni fi apere wiwo han sita. Ko si ohun ti o fa iye bikose pe won mo awon eto yi lori awon ipile ti ko pe, ti o ni adinku, won si tun mo lori awon irori omoniyan ti o ni enu aala ibi ti o ni agbara mo, eleyi ti iwoye re ko koja igi imu re, ti a ba ni ki a so ododo oro. A o maa wa lo owe ti o so pe: Ti o ba ranti ohunkan ti o mo, ti o si so o, aimoye ohunkan lo saimo re o.

Sugbon eyi ti o bori, ti o si ko gbogbo re tan ni pe won fi iye lele fun amuse awon afokante ati jije ere ise pelu gbigbe ola fun iran kan lori iran miran. Iye maa n ri bee nipa sise aseju nibi sise afomo enikookan lori opolopo eniyan tabi sise aseju lori opolopo eniyan ju ti afomo enikookan lo, tabi sise aseju nibi titi awon ohun elo siwaju emi, tabi titi emi siwaju ohun elo, bee si ni Islam duro laarin meji awon nnkan wonyi ni. Te eti si oro abiyi yi. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَكَذَلِكَ جَعَلْنَاكُمْ أُمَّةً وَسَطًا لِّتَكُونُواْ شُهَدَاء عَلَى النَّاسِ وَيَكُونَ الرَّسُولُ عَلَيْكُمْ شَهِيدًا" (سورة البقرة: 143)

“Baye ni A se se yin ni esa ijo to lore ju lo, nitori ki e le je elerii fun awon eniyan, ati nitori ki Ojise naa si le je elerii fun yin.” (Suurah al – Baqorah: 143)

Teti re si itosona Ojise Olohun (Ti ike ati Ola n be fun) ti o so fun awon sahabe re, nigbati o so fun Abdulahi Omo Umar (ki Olohun yonu si) pe: “Iwo Abdulahi, won fi to mi leti pe o maa n gba awe ni gbogbo osan, o si maa n dide kirun Nafilat ni gbogbo oru? Mo dahun wi pe: Beeni iwo Ojise Olohun, o dahun pe: Ma se maa fi gbogbo Osan gba aawe, maa ripe o nje losan lawon ojo kan, maa dide kirun nafilat ni awon abala die ninu oru, o si n sun ni abala die loru. Nitori pe ara re ni eto ti o gbodo pe fun – un, Oju re naa si ni eto ti O gbodo fun – un, Iyawo re naa si ni eto ti o gbodo fun – un.” (Imam Bukhari lo gba wa).

Nipa bayi, Emi je nnkankan to pamo fun awon to ri isemi si nkan ti o se pe ara lo gbe duro, ohun ti yio si maa nife si ko fi le maa dagbasoke si ni ohun jije, ohun mimu, aso wiwo, nnkan eelo, nnkan gigun, bakannaa igbiyanju lati wa iwosan nigbati o ba n se aisan nikan, igbagbe ninu emi ati fifun emi ni gbogbo ohun ti o ba nilo, nje eleyi le fa oriire bi?

Idahun ni pe “ko ri bee” Tori pe to ba le sokunfa orire ni opolopo ninu awon eniyan o ba ti pa okun so, awon ti won ri awon nkan igbadun aye ti ko se gbere, awon igabdun bii owo, iyi, ipo, ati gbajumo.

(Christiana Ornasyeas) ti o je omo obinrin kan soso (Millionarie) gbajumo olowo fun eni ti oruke re n je (ornasyes) eni ti n dari owo tabua eleyi ti o je pe latari owo yi o ni agbara ati le ri gbogbo igbadun aye. Awon olusewadi bi obinrin yii bileere wi pe: Nje iwo ni o roro ju lo ninu awon obinrin bi? O dahun pe: Beeni, Emi ni obinrin ti o ro oro ju lo, sugbon mi o ni isinmi, ti wahala mi si po ju lo larin awon obinrin. Won si so fun pe: Bi ara re pe, kinni idi ti o fi n so iru oro yi? “Emi maa fun o lasi pe: nitori pe o ti gbagbe emi ati awon ohun ti emi nilo ni. Nipa bayi emi wa nse aisan, o tun wa nko wahala ba si, sugbon ohun ti o rorun pupo ni oogun re, ohun eelo ti o ni alaafia ti a le fi koju e. bakanna nigba ti idaamu po pupo ni awon orile ede to koko gba iwaju ti won ni awon ohun amayederun orisirisi, ati awon idagbasoke ni (Europe) orile ede iroopu ni Pataki ju lo, orile – ede (Eugoslara) ugusi lafia eyi ti won lero pe ohun ni orile – ede ti o ro oro ju lo ninu awon orile – ede agbaye, yalaa oro ye wa ni ibamu si titobi orile – ede, tabi ni ibamu si awon eniyan kookan kookan ninu ilu, to n ti bee naa o si n mu idaamu lowo. Orile ede suwideen (Sweeden) fun apeere ohun ni orile ede ti o roro ju lo ti a ba wo bi awon eniyan kookan kookan ibe se rore to sugbon awon ni idaamu won p oju!! Labe bee ti a ba sakiyesi awon orile – ede Islam tohun ti opolopo awon eniyan se je alaini to, wahaala ti won n se kere jojo, ti o fee sun mo wi pe won o ti e ni idaamu Kankan, ka ni wipe a ko fee so pe idaamu won kere.

F. Filweas so pe: ipasofo emi n be ni iwo oorun aye, igbagbo kan ninu awon igbagbo ko ri aaye gba nibe Kankan, eyi ti yio mu won ri oriire, nipa bayi dukia ati ohun ti won n pe ni idera ti gbajumo nibe”. awon ohun ti anse ojukokoro re fun awon eniyan lawujo si wa lodo won, nipa bayi awon ti o wa ni owo iwo oorun aye won koye kogbo lati maa bi ara won ni awon ibeere wonyi: Kinni idi ti mo fi n semi? Ibo si ni mo n lo? Kin si ni idi e? Enikankan ko le dahun awon ibeere wonyi titi di isinsiyii.

Won o si mo wi pe ogun re nbe nibi sise esin, inu esin ti o duro daadaa lo wa. Won o mo niba esin ayafi awon ohun ti o ruju. Sugbon ibere imole esin ti bere si ni yo bayi o. Imole re si ti n tan kaakiri bayi, lila ojo si ti n yo bayi pelu bi awon ijo ijo se n wo inu Islam koda botile je pe awon diedie ni awon toun wo inu Islam Iabala iwo oorun aye. (Western part of the world). Awon eniyan ti o n gbe abala iwo oorun aye gan – an gan – an fi oju ara won ri aimoye awon okunrin ati obinrin ti won n tele ofin Islam daadaa ti won si n lo isemi pelu amulo ofin esin Islam, nipa bayi lojoojumo ni awon eniyan n wonu esin ododo diedie, ibere lasan si ni eri yi o. nipa bayi gegebi ara se maa n je ajeyo naa lo pondandan fun emi ki o je ajeyo. Ti ko ba waa je ajeyo, yio se aisan. Aisan ti yio si mu u ni awon aisan airi orun sun, ibanuje, airi idunnu ati idaamu, awon nnkan ti yio mu ni ajeyo ni: Alekun igbagbo si Olohun, igbagbo si bibe Olohun, igbagbo si igbende ati rirorun re, igbagbo ninu ojo ikeyin, Igbagbo ninu esan, Igbagbo ninu isiro ise, igbagbo ninu wi pe ododo ni sisele re ati mimu awon ijosin ti Olohun pa ase re wa, ati mimaa hu iwa rere ti won a file se agbega fun emi, eleyi si je ara ounje emi ti o sopo mo igbagbo. Bakanna Igbagbo (si Olohun) ni o le mu ki emi o la kuro nibi aisan. Airi orun sun, ati aibale okan, ti awon ara yio fi wa maa se aisan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِينَ آمَنُواْ وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُم بِذِكْرِ اللّهِ أَلاَ بِذِكْرِ اللّهِ تَطْمَئِنُّ الْقُلُوبُ" (سورة الرعد: 28)

“Awon ti won gbagbo ni ododo, ti okan won si bale nipa iranti Olohun, e gbo o!!! pelu iranti Olohun ni awon okan yio fi maa bale” (ar-Rad: 28)

Didamo iru eyi, ni awon Musulumi Olododo maa n gbadun ni tiwon. Iwo naa teti gbo nnkan ti Ibn Taymiyyah so (eni ti o je okan ninu awon Alfa ninu Islam) leyin ti won fi ara ni, tiwon ti ju si ewon, ti won si ti diya je pupo, ti won si ti da aya ja pe won yoo pa ni, sibesibe o tun n gbadun pelu ogidi oriire yii, oriire to je pe, enikan ko ni kapa lati ri, ayafi eni ti o ti ri adun igbagbo, Ibn Taymiyyah n be ni Ahere kan ni Damascus, leni ti won ju si ewon nibe. O si tun n so pe: “Awon ota mi kori nnkankan fi semi? ogba idera mi nbe ni igbaya mi, Ibikibi ti mo ba lo, n be pelu mi, won kofi mi sile rara, gbigbe mi de je pipasofo fun Ijosin fun mi, pipa mi, iku jijeri si okansoso Olohun ni, lile mi jade kuro nilu mi, irin ajo afe lo tun je”, ki eni ti won ju sewon tun le maa so iru oro bayi, E o ripe iyanu nla leyi je. Woye si bi igbagbo ododo se n sise, Ibn taymiyyah waadi oloriire ni ibi eyikeyi ipo ti o ba wa. Dajudaju Islam ni ohun fidi oriire emi ati ifokanbale emi mule daada fun gbogbo eni ti o ba se akolekan amulo ofun re, to si ni igbagbo ododo. Nipa bayi Musulumi gbogbo eyikeyi ipo ti o ba wa si ni oriire fun – un, yala o wa ni ipo alaafia, tabi ipo aisan, ipo oro tabi ipo aini, ipo ifokanbale tabi ipo ipaya. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُم مُّصِيبَةٌ قَالُواْ إِنَّا لِلّهِ وَإِنَّا إِلَيْهِ رَاجِعونَ * أُولَئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِّن رَّبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ وَأُولَئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ" (سورة البقرة: 156-157)

“Awon ti (o je pe) nigba ti adanwo kan ba kan won, won a so pe: “Dajudaju Olohun lo ni wa, dajudaju odo Re si ni a maa pada si * Awon wonye ni aforijin ati ike yo maa be fun lati odo Oluwa won. Awon wonye si ni olumona”. (Suurah al – baqorah: 156 - 157)

Ojise Olohun (ti ike ati Ola nbe fun) so pe: “Iyanu nla ni oro Olugbagbo ododo, tori pe gbogbo oro re, oore ni. Eleyi ko si le ri bee fun enikankan ayafi Olugbagbo ododo nikan. Ti o ba ri idunnu yoo dupe fun Olohun, eyi yio si je oore fun – un. Bakanna ti o ba tun ri inira, yoo se ifarada, eyi yio si tun je oore fun – un.” (Imam Muslim lo gbaawa).

Nipa bayi gbogbo eko ti Islam gbe wa ni won mopa lori iyonu ati ifarada, ti yio maa mu o gbagbe gbogbo ibanuje re, ti yio si maa gbe o kuro lati ipo jijakan kuro nibi ike Olohun ti yio si gbe o lo si ipo ero rere ati aba rere ni dida si ara a re. Olohun ti Ola Re ga so bayi ninu (Hadith qudsiy) mimo pe: (Bi erusin Mi ti se n ro nipa Mi naa ni mo se ri si i). Ibn hibaan lo gbaa wa.

Itumo eleyi ni pe: Emi Olohun yoo maa san erusin Mi lesan ni ibamu si ohun ti o ba ro nipa Mi. Ti o ba ni afokante ike Mi, ti o si lero pe Maa foju fo asise oun, Maa si fori ese jin oun, yoo ri ohun ti o gbero yi. Tori pe enikankan ko le ni iru ero bayi ayafi olugbagbo ododo nikan. Oun ni eni ti o mo wipe oun ni Olohun kan ti o maa n san esan. Bakannaa, ti o ba jakan kuro nibi ike Mi, ti o si ni lokan wi pe Maa fi iya je oun, yoo ri i bee looto. Tori pe enikan o ni jakan kuro nibi ike Olohun ayafi Alaigbagbo nikan. Koko oro yi, o ye ki a ta ara wa ji lori i re, E o ri Islam wi pe ki i pase ki eniyan kan mo sin Olohun lai wo ofin ti Olohun fi lele fun ijosin, ki i si pase jija kuro nibi ise aye, sugbon o maa n pepe lo sibi mimu oro aye tele ase Olohun, ki o fi le je ki a ri ogidi oriire. Nipa bayi eni ti o ba je Apase tabi Oludari, ki o maa ripe oun dari ijoba fi tele ase Olohun, ki o si fi ipo idari yi tan esin Re kale, ki o si fi ko oriire ba awon to ndari. Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun – un) sope: “gbogbo yin ni aderanje, gbogbo yin si ni a o bi, bi o se da eran re je si. Olori je Adaranje won yoo si bi i nipa awon to n dari, oko ninu ile naa je Adaranje fun awon molebi re, won yoo si bi i nipa awon to n dari, bakanna iyawo lodede oko re naa je Adaranje, won yoo si bi nipa awon to n dari, bakannaa omo – odo naa je Adaranje nipa owo oga re, won yoo si bi leere nipa bi o se mojuto eyi si. Mutafaq Alaei”. (Enu ko lori egbewa Hadith yi)

Eni ti o ba je onipo, ti o si ni iyi, ki o yaa maa lo ipo ati Iyi re yi fi tele ase Olohun, bakanna ki o si fi maa tan esin kale, ki o si maa lo lati fi biya bukata awon omo – Iya re ti o je Musulumi. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"مَّن يَشْفَعْ شَفَاعَةً حَسَنَةً يَكُن لَّهُ نَصِيبٌ مِّنْهَا وَمَن يَشْفَعْ شَفَاعَةً سَيِّئَةً يَكُن لَّهُ كِفْلٌ مِّنْهَا وَكَانَ اللّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ مُّقِيتًا " (سورة النساء: 85)      

“Enikeni ti o ba se ikunlowo ni ikunlowo daadaa, o maa ri ipin esan ninu re. Enikeni ti o ba si se ikunlowo ni ikunlowo aburu, o ma ri ipin ese ninu re. Olohun si je Oluso lori gbogbo nnkan” (Suurah a-n-Nisaa: 85)

Nipa bayi, eni ti o ba ni owo, ki o yaa maa na si oju ona Olohun, bakanna ki o maa fi toju awon Omo – Iya re, ki o si maa fi biya bukata won. Ibi ti oriire wa ni, ibi nina owo sojuona Olohun, ki i se ibi mimaa ko owo jo laina si oju ona Olohun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَفِي أَمْوَالِهِمْ حَقٌّ لِّلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ" (سورة الذاريات: 19)

“Ninu dukia won, won ni ojuse ti won n se fun alagbe ati eni ti A se arisiki ni eewo fun” (Dhaariyaat: 19)

Ojise Olohun (Ti Ike ati Ola n be fun) se alaye nnkan ti o maa n gbeyin owo ati dukia, o so pe: “Omo Adamo yoo ma so pe: Owo mi owo mi, nje nnkankan le je ti e bi, iwo omo Adam bikose pe owo ohun ti O je ni aje tan, tabi ohun ti o wo ti o si lo gbo, tabi nnkan ti o fi se sara ti won si ti fi esan re pamo sile fun o lodo Olohun.”

Ojise Olohun (Ti ike ati Ola n be fun) yii ni awokose fun gbogbo Musulumi oun ni eni ti o leto ki gbogbo Musulumi maa wo ilana re fi gbe igbese ni aye re. Abu Dharr ti soro nipa eyi, o so pe: “Mo n lo pelu Anabi (Ki ike ati Ola Olohun maa be fun un) ni agbegbe kan nilu Madinah, enikan ba pade wa, Ojise Olohun so pe: Iwo Abu Dharr, mo dahun pe mo n je ipe re Ojise Olohun, leyin naa o so pe: Ko si ohun ti o dunmo mi ninu to ki n ni goolu ti o to oke Huud yi, ti yio lo ojo meta pelu mi, ko tun wa je pe Diinaar kan yio tun seku simi lowo ayafi ki n yara na si ori esin nipa nina fun awon erusin Olohun to wa lotun, tabi ni egbe osi, tabi ti o wa ni eyin. Sugbon eniyan die ni n se bi eleyi”. (Bukhari lo gba a wa)

Ojuna ti Islam la kale fun eni ti o ba fee tele ofin Islam yii ojuona awon olusin Olohun ni, eleyi ti o si n fi ogidi oriire sise mule ni asiko ti kope tabi asiko ti o jinna die, Iye maa n rorun bee latari amulo awon eko ati imona ti Islam fi lele nipa awon ase Olohun, ati awon nnkan ti Olohun ko fun eniyan lati se, gbogbo awon ase ati awon ohun ti Olohun ko fun wa lati se wonyi, Olohun ko gbero inira tabi ifunpinpin Kankan lori i re, bikose pe amuse oriire ni ohun ti Olohun gbero lori i re, Iye je ohun ti a mo latari itumo nnkankan ni ibamu si nnkan kookan to wa ni ile aye yii, tori idi eyi awon ase Olohun ati awon ohun kiko Olohun, ninu re awon ohun atunse to dara pupo yala npa nnkan ti dara to lasiko ti ase yi wa lati odo Olohun tabi ni ojo iwaju, e je ki a se atupale awon nnkan ti Olohun pase re tabi ti o ko fun ni wonyi ni abe eyi, fun ki eni ti o ba fe ifeserinle leri ifirinle, ki iru eni yi si tun fi le ri fun ra re boya ofin to wa fun atunse ni tabi beeko. Gba awon yii bii apeere.

 

  • Ribba (Owo ele), eleyi je ohun ti Olohun soro nipa re bayi:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ اتَّقُواْ اللّهَ وَذَرُواْ مَا بَقِيَ مِنَ الرِّبَا إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ" (سورة البقرة: 278)

“Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Olohun, ki e si fi ohun ti o ku ninu ele sile, ti e ba je onigbagbo ododo” (Suurah al – Baqorah: 278)

Eleyi ko pamo rara fun gbogbo eni ti o ba ni oju – inu yio ri wi pe Ribba je ona lati je owo awon eniyan ni ti ibaje, eleyi si je ona eeru tori pe o je idina mo bibiya bukaata awon eniyan nibi abala siso owo na, tori pe o tumo si kiko owo jo latowo awon eniyan kan, ati gbigbe ipo awon kan ga bori awon miiran lawujo, eleyi ti awon miiran ti ki i se Musulumi gan – an n saa fun.

  • (Az – Zinna) agbere: Eleyi ni awon awujo eniyan ni abala iwo oorun aye n fi n se igbadun isemi, gbogbo awujo ti Zinna si fonka si ni o maa n ni abajade to buru, bii ki ajakale aisan kolu won, bii awon orisirisi iwa buruku miiran eleyi ti O ti n da opolo awon onilaakaye inu won laamu. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تَقْرَبُواْ الزِّنَى إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَسَاء سَبِيلاً" (سورة الإسراء: 32)

“E ma se sunmo Sina. Dajudaju o je iwa buruku. O si buru ni oju ona.” (Suurah al-Isroo: 32)

Ojise Olohun (Ki ike ati Ola maa be fun – un) so pe: “Ibaje Zinna koni gbale laarin awon eniyan kan botiwu ko o kere to ayafi ki aisan naa takan laarin won, igbona, ebi eleyi ti ko sele si awon eni isiwaju ri.” Ibn Ma’jah lo gbaa wa.

  • Oti mimu: Eleyi ti imo ise-ogun aye ode oni fi akoba re ti o nse fun ilera rinle, eleyi ti akoba re fun awujo ati eto isowona ti di ohun ti won ni ka sora fun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالأَنصَابُ وَالأَزْلاَمُ رِجْسٌ مِّنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ * إِنَّمَا يُرِيدُ الشَّيْطَانُ أَن يُوقِعَ بَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاء فِي الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ وَيَصُدَّكُمْ عَن ذِكْرِ اللّهِ وَعَنِ الصَّلاَةِ فَهَلْ أَنتُم مُّنتَهُونَ" {المائدة/90-91}

“Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju oti ati tete ati orisa ati ise yiyewo egbin ni ninu ise Esu. Nitori naa, e jina si i nitori ki e le jere * Ohun ti Esu n fe ni pe lati da ota ati ikorira sile laaarin yin nibi oti ati tete. O si fe seyin lori kuro nibi iranti Olohun ati nibi irun kiki. Se eyin o ni siwo (nibi ise Esu)?” (Suurah al – mio’idha: 90 -91)

  • Eran Elede Jije: Imo isegun aye ode oni ti fi rinle pe akoba buruku ni imaa je eran elede n se, toriwipe o n se okunfa awon opolopo aisan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"حُرِّمَتْ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةُ وَالْدَّمُ وَلَحْمُ الْخِنْزِيرِ وَمَا أُهِلَّ لِغَيْرِ اللّهِ بِهِ وَالْمُنْخَنِقَةُ وَالْمَوْقُوذَةُ وَالْمُتَرَدِّيَةُ وَالنَّطِيحَةُ وَمَا أَكَلَ السَّبُعُ إِلاَّ مَا ذَكَّيْتُمْ وَمَا ذُبِحَ عَلَى النُّصُبِ وَأَن تَسْتَقْسِمُواْ بِالأَزْلاَمِ ذَلِكُمْ فِسْقٌ الْيَوْمَ يَئِسَ الَّذِينَ كَفَرُواْ مِن دِينِكُمْ فَلاَ تَخْشَوْهُمْ وَاخْشَوْنِ الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الإِسْلاَمَ دِينًا فَمَنِ اضْطُرَّ فِي مَخْمَصَةٍ غَيْرَ مُتَجَانِفٍ لإِثْمٍ فَإِنَّ اللّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ" (سورة الـمائدة: 3)

“A se e eran okunbete ni ewoo fun yin, ati eje, ati eran elede, ati eyi ti won pa pelu oruko to yato si Olohun, ati eran ti won lumole ku, ati eran ti won kan pa ati eyi ti eranko abijawara je ku afi eyi ti e ba ri du (siwaju ki o to ku) ati eyi ti won pa sidii orisa. Eyin ko si gbodo fi nnkan ye ise wo. Iwonyi je ibaje. Lonii ni awon ti won saigbagbo soreti nu nipa esin yin. Nitori naa, eyin ko gbodo paya won. E paya Mi. Loni ni Mo pa ri esin yin fun yin. Mo si se asepe idera Mi fun yin. Mo si yonu si Islaam ni esin fun yin. Nitori naa, enikeni ti inira ebi ba mu (je eran eewo), yato si olufinnufindo – dese, dajudaju Olohun ni Alaforijin, Alaaanu.” (Suurah al – Moo’idah: 3)

Doctor Philiph Numas eni ti o mo nipa awon aisan inu eje, ti o n gbe London ti kii se Musulumi so pe: Elede maa gbe awon iroyin ara re wa fun eni ti o ba je eran re. Ti ojo ba pe lori jije re die, yio tun sokunfa awon aisan opolo ati awon aisan ara ni Pataki ju lo awon aisan awa a lo.

  • (AL – HUDUUD) ijiya ise si ofin: Eleyi ni awon ese ti Olohun so ofin ijiya mo, ti Elese ti o se iru awon ese bee maa je laye. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَكُمْ فِي الْقِصَاصِ حَيَاةٌ يَاْ أُولِيْ الأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ" (سورة البقرة: 179)

“Isemi n be fun yin nibi (ofin) igbesan ipaniyan, eyin onilaakaye, ki e le paya Olohun”. (Suurah al – Baqorah: 179)

Ododo ni oro Olohun ti o tobi ju lo, Isemi igbadun ati aabo fun awujo n be nibi amulo awon ofin ijiya ti o wa fun awon ese ti Olohun so ijiya re mo, pe ki a gbe ijiya re dide laye aabo tun wa nibe lori sise oselu, sise oowo na, pelu (gbigbe ijiya dide laye) Huduud leniyan fi n daabo bo emi, Omoluabi ati Owo pelu dukia. Gbogbo eto kookan ti ko ba ni agbara ofin ti yio dari re, ti yio gbe duro, ti yio si so eto naa daadaa maa n di pipati ni, bakannaa sise amulo re naa yio tun di ohun won o gbe jusile. Fun apeere ti danadana ba mo wi pe won ko le fi iya Kankan je oun, yoo maa da ona lo ni. Bakannaa, ti o le ba mo wi pe, won ko le fi iya Kankan je oun, yoo tepala mo ole ti n ja, yoo si maa balo ni. Maa fi eleyi won awon ese yoku miiran naa.

Uthman omo Affan, (ki Olohun ba ni yonu si) Olohun a maa fi ipo ase ko aburu eyi ti ki i fi Al – Qur’aan ko itumo eleyi ni pe a maa fi ipo ase ko iwa ibaje ju bi o se maa n fi Al – Qur’aan ko o lo, tori pe odaran yio tete beru idiyajeni ijoba ju bi yoo se beru idiyajeni ti Al – Qur’aan to se pe Ijiya orun ni ti tie.

Idi niye to fi je pe agbara amuse ofin maa n gbe eto duro, o si maa n da aabo bo o. nipa bayi ti ko ba si iru agbara bi eleyi ninu eto, eto naa o dabi awada ni, yio si di ohun ti won o ni le maa mulo, yi o si maa fa awuyewuye, yio si tun tan ibaje kale. Ati mo bayi pe amulo awon ofin Huduud, ki i se ohun akanfenu so, bi kose pe o wa ninu awon esin, to ti gba iwaju. Olohun ti Ola Re ga so ninu Al – Qur’aan leni ti o n so di e ninu awon eko Taorah.

"وَكَتَبْنَا عَلَيْهِمْ فِيهَا أَنَّ النَّفْسَ بِالنَّفْسِ وَالْعَيْنَ بِالْعَيْنِ وَالأَنفَ بِالأَنفِ وَالأُذُنَ بِالأُذُنِ وَالسِّنَّ بِالسِّنِّ وَالْجُرُوحَ قِصَاصٌ فَمَن تَصَدَّقَ بِهِ فَهُوَ كَفَّارَةٌ لَّهُ وَمَن لَّمْ يَحْكُم بِمَا أنزَلَ اللّهُ فَأُوْلَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ" (سورة الـمائدة: 45)

“Awa sise e ni ofin ninu re pe dajudaju emi fun emi, oju fun oju, imu fun imu, e ti fun eti ati eyin fun eyin? Ofin esan gbigba si wa fun oju – ogbe. Enikeni ti o ba si yonda igbesan, o si maa je ipesere fun. Enikeni ti ko ba dajo pelu ohun ti Olohun sokale awon won ye ni alabosi”. (Suurah al – Moo’idah: 45)

Ki enikokan maa beere lowo area a re, ko wa maa woye boya awon Ijiya ese ti Ilsam gbe wa lo sanfaani ju ni, ti o si lani lowo oran dida ju lo tabi o so oran dida di ewo ju lo, abi awon Ijiya ese ti omoniyan gbe wa fun ra a re eleyi ti o n je ki oran dida po si nikan bikose pe o tun n tan – an ka?

awon ye ni awon ofin ti won gbe kale lori fifun ikoja aala ni eto kan, ti o si fun eni ti won se ikoja aala si ni eto kekere. Bakanna ni won je ofin ti ko le dekun oran dida ni opolopo igba, o rorun ki awon eniyan so di ere tabi awada, Aye familete ki n tuto si ni ofin yii yio fi aaye gba awon kan.

Eleyi ko ni je ki eto awujo fi ese rinle rara, yala eto awujo ti aye ijoun tabi ti aye ode – oni. Nipa bayi, eyi ti o ga ju lati le dekun iwa ibaje tabi so iwa ibaje di niwon ni amulo idiyajeni gegebi Islam se gbe eto idiyajeni wa.

 

 

 

AMUSE OJULOWO ORIIRE NINU ISLAM

Ojulowo oriire ni eyi ti Islam gbe wa fun eni ti o ba se akolekan amulo awon ofin re ni abala awon origun esin to je mo igbagbo ipile ti i se:

 

ORIGUN AKOKO: IGBAGBO NINU OLOHUN ATI IJOKAN SOSO

"الَّذِينَ آمَنُواْ وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُم بِذِكْرِ اللّهِ أَلاَ بِذِكْرِ اللّهِ تَطْمَئِنُّ الْقُلُوبُ" (سورة الرعد: 28)

“Olohun ti Ola Re ga so pe: Awon ti won gbagbo ni ododo, ti okan won si bale nipa iranti Olohun. Kiye sii, nipa iranti Olohun ni awon okan yoo fi maa bale.” (Suurah a-r-Ra’d: 28)

Ti eniya ba mo titobi Olohun yi, Eni ti O ni ikapa lori gbogbo nnkan, ti o si ni agbara lori gbogbo nnkan, oun si ni eni ti ko si apejuwe iru re, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"اللّهُ لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لاَ تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلاَ نَوْمٌ لَّهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الأَرْضِ مَن ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلاَّ بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلاَ يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِّنْ عِلْمِهِ إِلاَّ بِمَا شَاء وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ وَلاَ يَؤُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ" (سورة البقرة: 255)

“Olohun, Ko si Olohun kan ti ijosin to si afi Oun nan, Alaaye, Alamojuuto eda. Oogbe ki i ta A. ati pe oorun ki i kun Un. TiRe ni ohunkohun ti n be ninu awon sanmo ati ohunkohun ti n be ninu ile. Ta ni eni ti o le sipe lodo Re bi ko je pelu ase Re? O mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be leyin won. Won ko si ni imo amotan nipa kini kan ninu imo Re afi ohun ti O ba fe (fi mo won). Aga Re gbaaye ju awon sanmo ati ile lo. Siso sanmo ati ile ko si da A lagara. O ga, O tobi”. (Suurah al – Baqorah: 255)

Igbagbo ninu Olohun ati ninu bibe Olohun ni o maa n je ki eniyan ri oriire to pamo sinu dida Olohun mo pelu origun to lagabra yii, ti o je origun ti eniyan yoo ma seri si ni gbogbo igba ti o ba ti n fe ki bukata kan biya, o je ohun ti o n fa oriire paapaa, origun igbagbo ninu Olohun naa si tun ni a maa n lo fun yiyege lasiko iso, Musulumi maa n lo origun yi lati fi se adua lopolopo igba. Olohun so pe:

"وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌ أُجِيبُ دَعْوَةَ الدَّاعِ إِذَا دَعَانِ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لِي وَلْيُؤْمِنُواْ بِي لَعَلَّهُمْ يَرْشُدُونَ" (سورة البقرة: 186)

“Nigba ti awon erusin Mi ba bi o leere nipa Mi, dajudaju Emini olusunmo. Emi yoo jepe ipe eni ti n sadau nigba ti o ba pe Mi. ki won tele ase Mi. ki won si gba Mi gbo nitori ki won le se konge itosona fun gbigba adua”. (Suurah al – Baqorah: 186)

Aini igbagbo ninu bibe Olohun Oba Adeda Olukapa lori gbogbo nnkan ni ori buruku lo wa, tori pe eni ti ko ba ni igbagbo ninu bibe Olohun, yoo maa lo isemi ninu igbedale okan lile ti Esu eyi ti o se pe ninu adamo okan gan – an nipe ohun naa ni igbagbo ninu bibe Olohun. Opolo pipe to ni alaafia si wa fun okan.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَمْ خُلِقُوا مِنْ غَيْرِ شَيْءٍ أَمْ هُمُ الْخَالِقُونَ" (سورة الطور: 35)

“Abi won da won lasan laisi Aseda? Abi awon ni wan da ara won?” (Suurah at – Tuur: 35)

A ti mo bayi pe igbagbo ninu Olohun, kosi iyemeji nibi wi pe igbagbo ninu Re somo imu Olohun lokan, ati ki a ma mu orogun mo – on. Eni ti o ba mu nnkan miiran mo, igbagbo ninu Oloohun re ko le se ni anfaani, ko si le ri aafaani kanakan pelu e. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ اللّهَ لاَ يَغْفِرُ أَن يُشْرَكَ بِهِ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَلِكَ لِمَن يَشَاء وَمَن يُشْرِكْ بِاللّهِ فَقَدِ افْتَرَى إِثْمًا عَظِيمًا" (سورة النساء: 48)

“Dajudaju Olohun ko nii forijin (eni ti) o ba n sebo si i. o si maa saforijin fun ohun miran yato si iye fun eni ti O ba fe. Eni ti o ba n sebo si Olohun, dajudaju o ti da adapa iro (ti o je) ese nla” (Suurah a-n-Nisaa: 48)

Iye ni pe mimu orogun mo Olohun, ko ko abuku kankan ba Olohun, tori pe Eni ti o ni adinku ko leto ki a gbe Ijosin fun – un, bawo ni won se fee maa sin eni ti oun gan – an n wa bukata si pipe.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لَوْ كَانَ فِيهِمَا آلِهَةٌ إِلاَّ اللَّهُ لَفَسَدَتَا فَسُبْحَانَ اللَّهِ رَبِّ الْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ" (سورة الأنبياء: 22)

“Ti o ba je pe awon orisa kan ti ijosin to si tun wa ninu sanmo ati ile leyin Olohun, sanmo ati ile o bati baje. Mimo ni fun Olohun, Oluwa (to da) ite – alarashi, o ga tayo iro ti won n pa (mon on).” (Suurah al – Anbiyaa: 22)

Nipa bayi Olohun ni Oloro, eni ti o da duro fun ara re, eni ti o ro oro tayo elomiiran, gbogbo eda yoku je alaini, ti won yoo wa bibiya bukata won si odo Olohun. Olohun ti Ola Re ga:

"مَا اتَّخَذَ اللَّهُ مِن وَلَدٍ وَمَا كَانَ مَعَهُ مِنْ إِلَهٍ إِذًا لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَهٍ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلاَ بَعْضُهُمْ عَلَى بَعْضٍ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ" (سورة الـمؤمنون: 91)

“Olohun ko fi eni Kankan se omo, ko si si Olohun kan pelu Re (Ti ko ba ri be e) nigba naa, Olohun kookan iba ti ko eda to da lo won iba si ti bori ara won (nibi itaporogan). Olohun mo tayo iro ti won n pa (mo on)” (Suurah al – mumiun 91)

 

NINU AWON ERE IGBAGBO NINU OLOHUN

Lila emi (mumini) Olugbagbo ododo kuro lowo didari ti elomiran, Nigba ti olugbagbo ododo bati mo amodaju wi pe gbogbo agbara pata ti Olohun ni i se, owo Re si ni ikapa gbogbo nnkan wa, ati pe kosi lowo eda Kankan botilewu ki eniyan ga to, tabi ni ipo to, kole ni agbara lati tako ohun ti Olohun ba gbero, tabi ki o se ohun ti Olohun Ko ba se. emi olugbagbo ododo ti tuwo patapata nibi mimaa sin nnkan miran yato si Olohun, nipa bayi yoo ma sin Olohun lori mimo amodaju pe Olohun nikan ni ijosin to si. Leni ti n wa iyonu Olohun Oba re nikan laini wa iyonu nnkan miran yato si Olohun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلْ مَن رَّبُّ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ قُلِ اللّهُ قُلْ أَفَاتَّخَذْتُم مِّن دُونِهِ أَوْلِيَاء لاَ يَمْلِكُونَ لإِنفُسِهِمْ نَفْعًا وَلاَ ضَرًّا قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الأَعْمَى وَالْبَصِيرُ أَمْ هَلْ تَسْتَوِي الظُّلُمَاتُ وَالنُّورُ أَمْ جَعَلُواْ لِلّهِ شُرَكَاء خَلَقُواْ كَخَلْقِهِ فَتَشَابَهَ الْخَلْقُ عَلَيْهِمْ قُلِ اللّهُ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ" (سورة الرعد: 16)

“Ta ni Oluwa awon sanmo ati ile?” So pe: Olohun ni” So pe: “Se leyin Re ni eyin yoo tun mu awon alafeyinti kan, ti won ko ni ikapa oore ati inira fun emi ara won?” so pe: “Se afoju ati oluriran dogba bi? Tabi awon okunkun ati imole dogba? Abi won yoo fun Olohun ni awon orogun kan ti awon naa da eda bii ti eda re, (to bee ge) ti eda fi daru mo won loju?” So pe: “Olohun ni Eledaa gbogbo nnkan. Oun si ni Okan soso, Olubori”. (Suurah a – Ra’d: 16)

Itusile emi Olugbagbo ododo nibi biberu nnkankan ayafi Olohun nikan soso, nipa bayi ki eniyan beru nnkan miran yato si Olohun maa n fa ori buruku ni, o si maa n da isemi eniyan ru, tori pe Esu yoo bere si ni maa n da isemi eniyan ru, tori pe Esu yoo bere si ni maa mu eniyan sere, yoo si maa fi gbogbo nnkan seruba a, nipa bayi, esu yoo ba ju iru eni be sinu ifunpinpin ati idaamu. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّمَا ذَلِكُمُ الشَّيْطَانُ يُخَوِّفُ أَوْلِيَاءهُ فَلاَ تَخَافُوهُمْ وَخَافُونِ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ" (سورة آل عمران: 175)

“Dajudaju iye ni Esu, ti n fi awon ore re deru ba yin. Nitori naa, e maa se beru won. Ki e si beru mi ti e ba je Onigbagbo ododo” (Suurah aali Imroon: 175)

Gbigbe akin wo inu emi: nipa bayi eni ti o ba gba Olohun gbo, ti o si gba pe oun ni Olohun tii maa je ki eda maa semi, tabi ki emi maa ku, ati pe owo re ni ikapa gbogbo oro wa. Okan iru eni bee yio bale, oriire eleyi je oriire kan ti a sopo mo oore ti torun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا كَانَ لِنَفْسٍ أَنْ تَمُوتَ إِلاَّ بِإِذْنِ الله كِتَابًا مُّؤَجَّلاً وَمَن يُرِدْ ثَوَابَ الدُّنْيَا نُؤْتِهِ مِنْهَا وَمَن يُرِدْ ثَوَابَ الآخِرَةِ نُؤْتِهِ مِنْهَا وَسَنَجْزِي الشَّاكِرِينَ" (سورة آل عمران: 145)

“Ko to fun emi kan lati ku afi pelu ase Olohun (Iku je) akosile onigbedeke. Enikeni ti o ba n fe esan (ni) aye. A maa fun un ni aye. Enikeni ti o ba nfe esan (ni) orun, A maa fun un ni orun. A o si san awon oludupe ni esan.” (Suurah aali – Imroon: 145)

Didoju ko Olohun nigba gbogbo ni orisun ati ipile gbogbo oore.

"لَهُ مَقَالِيدُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ أُوْلَئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ" (سورة الزمر: 63)

“TiRe ni kokoro (oro) awon sanmo ati ile, awon ti won saigbagbo ninu awon aayah Olohun, awon wonye ni awon eni ofo”. (Suura az-Zumor: 63)

Sugbon eni ti koni igbagbo ninu Olohun, iru eni bee yoo lo isemi oloriburuku, nitori pe yoo maa yi ninu okunkun aimokan ati okunkun aigbagbo, pelu aini igbagbo ododo ko si ipile kan ti yoo le maa gbe ara le, ti yoo si le maa duro le lori. Ododo ni oro Olohun ti Ola re tobi to sope:

"فَمَن يُرِدِ اللّهُ أَن يَهْدِيَهُ يَشْرَحْ صَدْرَهُ لِلإِسْلاَمِ وَمَن يُرِدْ أَن يُضِلَّهُ يَجْعَلْ صَدْرَهُ ضَيِّقًا حَرَجًا كَأَنَّمَا يَصَّعَّدُ فِي السَّمَاء كَذَلِكَ يَجْعَلُ اللّهُ الرِّجْسَ عَلَى الَّذِينَ لاَ يُؤْمِنُونَ" (سورة الأنعام: 125)

“Enkeni ti Olohun ba fe fi ona mo. O maa si igba – aya re fun Islaam. Enikeni ti o ba si fe si lona. O maa fun igbaaya re pa (ti o maa ha) gadigadi bi eni pe o n gunke lo sinu sanmo. Baye ni Olohun se de whaala asan si awon ti ko gbagbo” (Suurah al – Ani’aam: 125)

 

ORIGUN KEJI: IGBAGBO NINU AWON MOLAIKA

Awon molaika je eda ti o wa ni agbaye to pamo, ko rorun lati mo won ayafi ti o ba je pe a gba ona odo awon ojise tiwo n mu ise wa lati odo Olohun Oba ti mimo ati giga je ti Re. awon ise kan n be ti Olohun ti gbe fun awon Malaika lotooto, lati laa bowon lorun pe ki won maa mojuto, lati odo won si ni Ise ase soriire ni ti papa oriiire ti n sokale si ori ile aye. Eni ti Olohun la ise mimaa mu ise wa fun awon Ojise Olohun bo lorun ni Jibril (Ki ike ati Ola Olohun maa be fun un). Awon Ojise naa si maa n mu ise yi de odoo awon eniyan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ آمِنُواْ بِاللّهِ وَرَسُولِهِ وَالْكِتَابِ الَّذِي نَزَّلَ عَلَى رَسُولِهِ وَالْكِتَابِ الَّذِيَ أَنزَلَ مِن قَبْلُ وَمَن يَكْفُرْ بِاللّهِ وَمَلاَئِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ فَقَدْ ضَلَّ ضَلاَلاً بَعِيدًا" (سورة النساء: 136)

“Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ni igbagbo ododo ninu Olohun ati Ojise Re, ati Tira ti (Olohun) sokale fun Ojise Re, ati Tira ti O sokale siwaju. Enikeni ti o ba saigbagbo ninu Olohun ati awon Molaaika re ati awon Tira Re, ati awon Ojise Re ati Ojo ikeyin dajudaju. O ti sina ni isina to jinna tefetefe”. (Suura an-Nisaa: 132)

 

ORIGUN KETA: IGBAGBO NINU AWON TIRA EYI TI O SOKALE LATI ODO OLOHUN

Eleyi ni ilana eyi ti Olugbagbo ododo yoo maa tele ni aye re, ibe si ni yoo ti maa ri ounje emi, ti yio fi rorun fun emi lati maa da awon ise rere ati ilana ijosin mo, yala ijosin ti o ma n wa ninu emi tabi ninu ise. Latari imaa samulo ofin inu awon tira wonyii ni ifidimule daadaa fi le maa lo ni awujo, ti ifokanbale emi yio si wa, ti eto isowonaa lona to dara ati eto isejoba lona to dara fi le wa Olohun ti Ola Re ga so pe:

"مَنْ عَمِلَ صَالِحًا مِّن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَى وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَنُحْيِيَنَّهُ حَيَاةً طَيِّبَةً" (سورة النحل الآية 97)

“Enikeni ti o ba se ise rere ni okunrin tabi ni obinrin, o si je onigbagbo ododo, dajdudaju. A oo je ki o lo igbesi aye to dara”. (Suurah an – Nahl: 97)

Dajudaju o ti wa fun awon eko ti Islam ko wa, rire Musulumi sibi awon iwa alaponle, ati ilapa totobi nibi koje okunfa oriire fun – un bakannaa yio tun gbe oluse rere jinna si awon iwa idoti ti awon ti ko ni esin maa n fi lo isemi won. Eyi ti o po ninu awon wonyi si ni esin won ko ni le fun won ni ifesemule emirere, ati ifokanbale emi nitoripe o ti ropo mo esin won, awon darudapo ati awon itako nnkankan si nnkan miiran.

NINU AWON EKO TI ISLAM PA MUSULUMI LASE LATI MU LO NIWON YII:

 

Nini ife Olohun ati Ojise Re: Dajudaju nini ife Olohun ati Ojise Re je ohun ti O maa gbe Musulumi lo sibi ki O lo gbogbo ohun ti Olohun ba fun – un si ojuona Olohun ti o nife si yi.

Nipa bayi yoo maa waa wa ninu oriire kan ti kosi afiwe re ninu gbogbo oriire, lopin igba ti o ba tin nsise lati ri iyonu Olohun to nife. Ni ile aye yi gan – an, o maa ri enikan ti yoo ma nife si elomiiran, ti yoo si maa ti tori idi eyi maa na gbogbo ohun ti o ba ni lagbara lati na, ki o file ri iyonu eni ti o nife si yi, ti yoo si maa ri adun nibi amuse gbogbo nnkan to n wa latari eyi. Bawo lo se wa lero pe ti iru ife bayi ba wa je ti eniyan si Olohun Oba ti o gbon n gbon, Oba Alaponle ju lo, Oba ti o gba iroyin ti o pe lori gbogbo nnkan. Bakannaa Ojise Re (TI IKE ATI OLA N BE FUN) si ni eniti oni ola ju ninu gbogbo eda Oloohun ti mimo n be fun ti ola Re si ga julo n so iroyin ojulowo ife eyi ti awon olugbagbo odod ni si i.

Olohun so pe:

"وَمِنَ النَّاسِ مَن يَتَّخِذُ مِن دُونِ اللّهِ أَندَاداً يُحِبُّونَهُمْ كَحُبِّ اللّهِ وَالَّذِينَ آمَنُواْ أَشَدُّ حُبًّا لِّلّهِ وَلَوْ يَرَى الَّذِينَ ظَلَمُواْ إِذْ يَرَوْنَ الْعَذَابَ أَنَّ الْقُوَّةَ لِلّهِ جَمِيعاً وَأَنَّ اللّهَ شَدِيدُ الْعَذَابِ" (سورة البقرة: 165)

“O si n be ninu awon eniyan, eni ti n josin fun awon orisa leyin Olohun. Won nifee won gege bi ife (ti o ye ki won ni si) Olohun. Awon ti won gbagbo ni ododo si le ju lo ni ife (ti won ni) si Olohun. Ti o ba je pe awon ti won se abosi le ri igba ti won maa ri Iya naa ni, (won o ba mo pe) dajudaju gbogbo agbara n je ti Olohun. Ati pe dajudaju Olohun le (nibi) iya.” (Suurah al – Baqorah: 165)

Iru ife yi gan – an ni awon sahabe (ki Olohun ba ni yonu siwon lapapo) ni, ti won si fi lo isemi won. E je ki a wo sahabe Pataki kan ti oruko re n je Khubaeb omo Udayy (ki Olohun ba ni yonu si i) Nigba ti awon osebo mu leru, ti won si bi leere pe: Nje o ni bukata kan lati gbo ki o to ku bi? Nipa bayi, o toro ki won lo oun lara ki oun fi ki irun Nafilat Raka’at meji. Fun idi eyi, won yonda lati lo lara ki o fi ki irun Rakat meji. Nipa bayi, oun ni o je eni akoko ti o je ki a maa yan Nafilat Raka’t meji ki won o to pani. Leyin ti o kirun tan, o so pe: “Mo fi Olohun bura, ti o ba je pe moun beru iku fun pipa ti e fee pami ni mi o ba fa irun naa gun ni. Nigabti won gbe de ibi ti won a ti kan mo igi lati ge ori re bo sile, won bi i leere pe: Se o nife si ki a gbe Muhammad wa lati ropo re nibi ti o wa yi, ki a si tu iwo sile ki o maa lo si odo ebi re layo? O dahun pe: mo fi Olohun bura mi o le nife si ki egun kekere kan gun Muhammad (TI IKE ATI OLA N BE FUN) ninu ile lodo awon ebi re, ki emi si wa ni aaye ti mo wa yi. Itumo eleyi ni pe, o so pe ki n maa wa ni aaye mi yi, ki n maa je iya ti mo n je yi ro mi lorun ju ki egun kan gun Muhammad (TI IKE ATI OLA N BE FUN) ni odo awon molebi ninu ile nitori ki iye le je iropo iya ti mo n je lowolowo bayi.”

Olori buruku ni eni ti o koko ti ife inu ati oju kokoro siwaju ife tolohun ati iyonu Re. Olohun oba ti Ola Re ga so pe:

"قُلْ إِن كَانَ آبَاؤُكُمْ وَأَبْنَآؤُكُمْ وَإِخْوَانُكُمْ وَأَزْوَاجُكُمْ وَعَشِيرَتُكُمْ وَأَمْوَالٌ اقْتَرَفْتُمُوهَا وَتِجَارَةٌ تَخْشَوْنَ كَسَادَهَا وَمَسَاكِنُ تَرْضَوْنَهَا أَحَبَّ إِلَيْكُم مِّنَ اللّهِ وَرَسُولِهِ وَجِهَادٍ فِي سَبِيلِهِ فَتَرَبَّصُواْ حَتَّى يَأْتِيَ اللّهُ بِأَمْرِهِ وَاللّهُ لاَ يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ" (سورة التوبة: 24)

“Ti o ba je pe awon baba yin, awon omokunrin yin, awon omo iya yin, awon iyawo yin ati awon ibatan yin pelu awon dukia kan ti e ti ko jo ati oko-owo kan ti e n beru pe ki o ma kuta ati awon ibugbe ti e yonu si (ti iwonyi) ba wu yin ju Olohun ati Ojise Re, ati jija ogun fun esin Re, e maa re ti nigba naa titi Olohun yoo fi mu ase Re wa Olohun ko si ni fi ona mo ijo obileje”. (Suurah a-t-Taobah: 24)

           

imaa nife si nnkan nitori Olohun ati Ojise Re: Eni ti o ba feran nnkankan nitori Olohun, o nanwo nitori Olohun, o tore, o peran Ileya nitori Olohun, titi ti awon daadaa won yi fi di ekejji re, irufe awon wonyi ni eyikeyi ohun ti won (tanmo – on) fokante ninu oore aye ko ni le gba ife Olohun yi lemi won, bikose pe ife yi o maa lo gbere lati le fi wa iyonu Olohun, Nipa bayi Musulumi o maa wa da oriire mo nitoripe o ti mo wi pe awon elominran to nferan oun, n feran oun nitori Olohun ni, ki i se titori daadaa oore aye ti o n ri kojo laye.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَالَّذِينَ تَبَوَّؤُوا الدَّارَ وَالإِيمَانَ مِن قَبْلِهِمْ يُحِبُّونَ مَنْ هَاجَرَ إِلَيْهِمْ وَلاَ يَجِدُونَ فِي صُدُورِهِمْ حَاجَةً مِّمَّا أُوتُوا وَيُؤْثِرُونَ عَلَى أَنفُسِهِمْ وَلَوْ كَانَ بِهِمْ خَصَاصَةٌ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفْسِهِ فَأُوْلَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ" (سورة الحشر: 9)

“Awon ti won n gbe inu ilu Modinah siwaju won, ti won si ni igbagbo ododo won nifee awon ti won fi ilu Mokkah sile wa si odo won (ni ilu Modinah). Won ko si ni (keeta) kini kan ninu igba – aya won nipa nnkan ti won fun won. Won si n fe won ju emi ara won lo, koda ki o je pe awon naa ni bukata gun si (Ohun ti won fun won). Enikeni ti Won ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonye ni awon olujere”. (Suurah – al – Hashr: 9)

Ojise Olohun ti ike ati Ola n be fun so pe: “Nnkan meta kan n be ti o je pe ti eniyan ba ni yoo ri adun igbagbo, ki o je pe Olohun ati Ojise Re nikan ni yoo nife si ju lo, ati ki o je pe ti o ba maa feran eniyan kan, ki o je pe yoo feran re nitori Olohun, ati pe ki o maa korira a ti pada sinu aigbagbo gegebi o se korira a ti wo ina”. (apanupo bukhari ati muslim)

Itumo adun igbagbo ni sisipaya igbaaya fun igbagbo, ati igbadun pelu titele ase, ati fifi ara da idaamu lori esin.

Dajudaju fifi idi ife yi mule ni awon ona ti yio la eniyan nibi wahala ati idaamu ojo idajo ti yio waye laariin awon eniyan. Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so pe: “Orisi eniyan meje kan n be ti won o wa ninu iboji Olohun, ni Ojo ti ko nii si iboji miiran ayafi iboji Olohun nikan, awon naa ni (Imaam) Asiwaji onideede, odo ti o dagba sinu Ijosin Olohun re, Okunrin kan ti a se akolekan ki o maa saaba wa ni Mosalasi, awon okunrin meji kan ti won ni ife ara won nitori Olohun, ati Okunrin kan ti obinrin kan ti o ni ipo ati ewa pe ki o wa ba oun se Zina ti okunrin yi si so fun – un pe, emi n beru Olohun (nipa bayi o ko lati se Zina), ati okunrin kan ti o se sara ti o si se e ni bonkele titi ti owo – osi ko fi mo ohun ti owo otun n na, ati okunrin kan ti o ranti Olohun ni koro, ti omi ekun si n da loju re” (apanupo bukhari ati muslim).

 

ima gbe ijosin fun Olohun nikan: Oriire ati iyi pupo lowa nibi ki Musulumu je erusin fun Olohun yato si eni ti o je erusin fun ojukokoro re, nipa bayi o fi wa dunnimo ododo siso, ti o fi wa n tele ase ti Olohun ba pa a, bakannaa o n ko fun ara re, ohunkan ti Olohun ba ko, ti o wa n se bayi lati wa ojulowo oriire, nitori pe ife ati ijosin fun Olohun ti bori ojukokoro ti o ni, o si ti bori Esu, ati ewu pelu ijamba Esu ati royiroyi re. Nipa bayi awon eko ti Islam ko wa, ti je ki Musulumi mo pe gbogbo asiko oun, owo oun, dukia oun, igbiyanju oun ati gbogbo isemi oun patapata je ohun ti oun ju sile fun itele ase Olohun.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلْ إِنَّ صَلاَتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ " (سورة الأنعام:162)

“Dajudaju irun mi, eran mi, (ti mo n pa): Isemi aye mi ati iku mi n je ti Olohun Oluwa gbogbo eda.” (Suurah al – An’aam: 162)

Kii se eda abara nikan ni o to si ki o maa josin, bi kose pe gbogbo eda, eleyi ti Awon Anabi Olohun, awon Ojise Olohun ati awon Malaika naa wa ninu won.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لَّن يَسْتَنكِفَ الْمَسِيحُ أَن يَكُونَ عَبْداً لِّلّهِ وَلاَ الْمَلآئِكَةُ الْمُقَرَّبُونَ وَمَن يَسْتَنكِفْ عَنْ عِبَادَتِهِ وَيَسْتَكْبِرْ فَسَيَحْشُرُهُمْ إِلَيهِ جَمِيعًا" (سورة النساء: 172)

“Mosiih (anobi isa) ko ko lati je eru fun Olohun. Bee naa ni awon Molaaika ti won sunmo Olohun. Enikeni ti o ba ko lati josin fun un, Ti o tun segberaga (Olohun) yoo ko won jo papo patapata si odo Re.” (Suurah a-niNisah: 172)

Bi kosepe, gbogbo aye patapata ni o to si won ki won maa sin Olohun, ki won o si maa teriba fun – UN, eleyi si wa lara ohun ti n tokasi titobi Olohun Adeda ti o je Eni ti ijosin tosi.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"تُسَبِّحُ لَهُ السَّمَاوَاتُ السَّبْعُ وَالأَرْضُ وَمَن فِيهِنَّ وَإِن مِّن شَيْءٍ إِلاَّ يُسَبِّحُ بِحَمْدَهِ وَلَكِن لاَّ تَفْقَهُونَ تَسْبِيحَهُمْ إِنَّهُ كَانَ حَلِيمًا غَفُورًا" (سورة الإسرراء: 44)                

“Awon sanmo mejeeje ati ile ati awon ti o wa ninu won n se afomo fun Un. Ko si si kini kan afi ki o maa se afomo pelu idupe fun Un. Sugbon eyin ko le gbo agboye (bi won se n se) afomo won, Dajudaju (Olohun) nje oni suuru, Alaforijin” (Suurah al – Isroo: 44)

Eni ti o ba seri kuro nibi jijosin fun Olohun, kole ri nnkankan nibe bikose oriburuku ati isemi ifunpinpin, nitori pe, irufe eni be n sise laini afojusun niye, kosi le ri oriire iru eyi ti awon eni ti o gbe paapaa ijosin fun Olohun nikan soso.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَنْ أَعْرَضَ عَن ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَى" (سورة طه: 124)

“Enikeni ti o ba si seri kuro nibi iranti mi dajudaju isemi inira ni o maa gbe laye. A si maa gbe e dide ni Ojo Ajinde ni afoju”. (Suurah Toohaa: 124)

Eni ti ko ba le je erusin fun Olohun, yoo pada je erusin fun Esu.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَن يَعْشُ عَن ذِكْرِ الرَّحْمَنِ نُقَيِّضْ لَهُ شَيْطَانًا فَهُوَ لَهُ قَرِينٌ" (سورة الحجر: 39)

“Enikeni ti o ba gunri kuro nibi iranti (Olohun) Ajoke aye, A maa yan esu kan fun un. Oun si ni alabaarin re”. (Suurah Zukruf: 36)

Esu yii ko ni fa omoniyan lo sibi nKankan ayafi ibiti yoo ti ko oriburuku ba, ti omoniyan yoo fi koja aala Olohun, gegebi ileri re, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قَالَ فَبِمَا أَغْوَيْتَنِي لأَقْعُدَنَّ لَهُمْ صِرَاطَكَ الْمُسْتَقِيمَ " (سورة الـحجر: 39)

“O wi pe: Oluwa mi, fun wi pe O ti se mi ni eni anu, dajudaju emi yoo se (aburu) ni oso fun won ni ori ile, Dajudaju emi yo si ko gbogbo won sinu isina” (Suurah al – Hijr: 39)

Dajudaju oriire kan to pamo ni sisin Olohun, eni kan ko ni le da eyi mo ayafi eni ti o ba n gbe ijosin fun Olohun nikan soso, E je ki a teti si oro enikan ninu awon Musulumi ti o da oriire yi mo nitori gbigbe ijosin fun Olohun nikan: “Ti awon olola, awon oba aye, ati awon omo oba ba lo mo iru igbadun ti a n ri (nibi jijosin fun Olohun nikan) won o ba fi ida gbogun ti wa”.

 

Irinle agboye ohun ti n je ojulowo oriire laelae ninu emi Musulumi: E ri oriire laelae ni ti paapaa kosi laye, orun ni o wa. Fun eni ti Olohun ba fi se konge oriire ti o fi le wo Alujannah. Eleyi si ni afojusun ti o ga ti Musulumi maa n fe, ki i se ohunkan miiran. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَأَمَّا الَّذِينَ سُعِدُواْ فَفِي الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ السَّمَاوَاتُ وَالأَرْضُ إِلاَّ مَا شَاء رَبُّكَ عَطَاء غَيْرَ مَجْذُوذٍ" (سورة هود: 108)

“(Amo) ni ti awon ti A ba se ni olori – ire, won maa wa ninu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re, ni odiwon igba ti awon sanmo ati ile fi n be” (Suurah Huud: 108)

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Ile – Aye je ewon fun Olugbagbo ododo, o si je ogba Idera fun keferi”. (Imam Muslim lo gba a wa).

Itumo re ni wipe ewon ni aye je fun olugbagbo ododo, won ti ko fun Olugbabo ododo lati se awon nnkan ti yio maa wu emi re lati se, won si ti la won nnkan kan bo lorun lati maa se.

Eleyi le sokunfa ki awon ibeere kan wa sinu opolo wa, bii ki eniyan maa bere lowo ara re pe: “Bawo ni Oro yi se le je bee tori pe a n ri opolopo awon keferi ti won n gbe ile aye ifunpinpin ti okan won ko bale ti a sin ri opolopo Musulumi ti o n gbe aye Igbadun, onifokanbale?” E je ki n so itan kekere kan ti Ibn Hajar Al – Asqolaaniy (Ki Olohun ba ni kee) Oun ni olori awon Adajo ni ilu Misroh, tori pe idahun ti o ya ni lenu si awon ibeere yii wa nibi itan naa.

Ibn Hajar jade pelu imura ti o kun fun oso ni ojo kan, o wa koja legbe okunrin Yahuudiy kan ti o wa ni ipo alairi aso wo, ti o tumo si pe alaini olosi ni. Okunrin Yahuudi yi ba so fun Adajo (Ibn Hajar Al – Asqolaani) ki o duro. Nipa bayi Ibn Hijar ba duro. Okunrin Yahuudi yi ba so fun – un pe: Bawo ni o se tumo oro Ojise yin yii si “Ile aye ewon ni fun Olugbagbo ododo, ogba idera si ni o je fun keferi”. Se o ri emi pe mo je Alaini, Alairasowo, mo si je keferi. Iwo si n be ninu igbadun ati oso tohun ti bi o tun se je Olugbagbo Ododo? Nipa bayi Ibn Hajar dalohun pe: Tohun ti bi o se je Alaini Olosi won a gbe o sipo eni ti o wa ni Alujannah, nitoripe awon iya Eleta – Elero ti n duro de o ni orun ti o ba ku sori keferi re yi, sugbon emi, tohun ti bi mo se wa ninu Igbadun ati oso, ti Olohun ba fi le fimi sinu Alujannah, gbogbo ike ati igbadun Ile aye yi maa di ohun ti won o kaa si igbadun inu ewon ni ti a ba fi won igbadun ati ike ti o n duro demi ninu Aljunnah. Okunrin Yahuudi yi wa beere pe: Se bi oro se ri niye? Ibn Hajr dahun pe: Beeni. Awon oro yi si lo se okunfa gbigba Islam fun okunrin Yahuudi naa. Islam mu oro ile aye ni kekere fun Musulumi, o si salaye idi ti aye fi yepere, ki Musulumi fi le jinna si gbogbo ohun ti o le da okan re ru ninu awon adanwo ile aye ati awon idojuru nnkan ni aye, Ojise Olohun (Ti ike ati Ola n be fun) ti fun wani iroyin eleyi ninu Hadith ti Sahlu Omo Saad gba wa. O so pe: “Awa pelu Ojise Olohun (TI IKE ATI OLA N BE FUN) ni Dhul – Hulaifah, lojijii ni a ri oku ewure kan ti ese re ti wu ga soke fun fifon ti won fon. Leyinnaa Ojise Olohun sope: bawo ni isesi eran yi wa lodo olowo re? nitoripe o ti di oku – n – bête. Mo fi Olohun ti o ni ikapa emi mi bura, Ile aye yepere ni odo Olohun ju bi Oku eran yi se yepere lodo olowa re lo, ti o ba je pe aye won osunwon ti o to iye efon lodo Olohun ni, keferi ki ba ti ri ekikan omi kan mu ni ile aye laelae”. (Ibn Majah lo gba a wa).

 

Alaye wipe Awon Ojise Olohun ati awon Anabi Olohun ni eni – esa ju lo ninu eda Olohun, awon si ni Olohun feran ju ninu eda, Olohun o si fi igbadun aye royin won, won o si mori bo kuro nibi idaamu ati isoro aye ninu isemi won, o nbe ninu won eni ti won pa, oun be ninu won eni ti won diya nla je, n be ninu won eni ti won se ni suta, ti won fi ara ni, n be ninu won eni ti won le kuro ninu ilu re, n be ninu won eni ti won pa iro mo, n be ninu won eni ti won pe ni opidan, n be ninu won eni ti won pe ni were. Ti o ba ri bee, a je pe awon eniyan miiran ti won je olukoja aala Olohun gan – an ni awon isoro won yi tosi ju.

Olohun ti Ola Re ga so nipa iroyin Anabi Nuh:

"وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَى قَوْمِهِ فَلَبِثَ فِيهِمْ أَلْفَ سَنَةٍ إِلاَّ خَمْسِينَ عَامًا فَأَخَذَهُمُ الطُّوفَانُ وَهُمْ ظَالِمُونَ" (سورة العنكبوت: 14)

“Dajudaju A ran (Anabi) Nuuh nise si awon eniyan re. o gbe laaarin won fun egberun odun, o din ni aadota odun. Ekun – omi gbe won lo, (nitori pe) alabosi ni won”. (Suurah al – Anbkabuut: 14).

Olohun Oba so nipa Anabi Ibrahim:

"فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلاَّ أَن قَالُوا اقْتُلُوهُ أَوْ حَرِّقُوهُ فَأَنجَاهُ اللَّهُ مِنَ النَّارِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ" (سورة العنكبوت: 24)

 “Esi awon eniyan re ko je kinni kan tayo pe won wipe: E paa tabi ki e sun un ninu inan, Olohun si laa ninu Ina. Dajudaju awon ami kuku wa ninu iye fun ijo to ni igbagbo ododo” (Suurah al – Ankabuut: 24)

Olohun Oba so nipa Anabi Musa:

"وَقَالَ فِرْعَوْنُ ذَرُونِي أَقْتُلْ مُوسَى وَلْيَدْعُ رَبَّهُ إِنِّي أَخَافُ أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمْ أَوْ أَن يُظْهِرَ فِي الأَرْضِ الْفَسَادَ" ( سورة غافر: 26)

“Fir’aon wi pe “E ju mi sile ki ng pa Muusaa, ki o si pe Oluwa re (wo boya O maa gba a sile). Dajudaju emi n beru pe o maa yi esin yin pada tabi pe o maa tan ibaje ka lori ile”. (Suuratu gaafir: 26)

Olohun Oba so nipa Anabi Su’aeb.

" قَالَ الْمَلأُ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُواْ مِن قَوْمِهِ لَنُخْرِجَنَّكَ يَا شُعَيْبُ وَالَّذِينَ آمَنُواْ مَعَكَ مِن قَرْيَتِنَا أَوْ لَتَعُودُنَّ فِي مِلَّتِنَا قَالَ أَوَلَوْ كُنَّا كَارِهِينَ " (الأعراف: 88(

“Awon agbaagba ti won segberaga ninu ijo re wi pe: “Dajudaju awa yoo le iwo Su’aeb ati awon ti won gbagbo pelu re jade kuro ninu ilu wa tabi ki o pada sinu esin wa”. (Su’aeb so pe: “Se (e maa da wa pada sinu iborisa) to si je pe emi wa ko o?” (Suurah Al – ‘a’ raaf: 88)

Olohun Oba so nipa Anabi Soolih:

"قَالُواْ يَا صَالِحُ قَدْ كُنتَ فِينَا مَرْجُوًّا قَبْلَ هَذَا أَتَنْهَانَا أَن نَّعْبُدَ مَا يَعْبُدُ آبَاؤُنَا وَإِنَّنَا لَفِي شَكٍّ مِّمَّا تَدْعُونَا إِلَيْهِ مُرِيبٍ" (سورة هود: 62)

“Won wi pe: “Iwo Soolih, o ti lo laarin wa ni eni ti a ni ireti si pe iwo yoo sanjo) siwaju (oro ti o so) yii. Se iwo yoo ko fun wa lati maa josin fun ohun ti awon baba njosin fun, dajudaju awa wa ninu iyemeji gbopon nipa nnkan ti o n pe w a si” (Suurah Huud: 62)

Olohun Oba so nipa Anabi luut

"فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلاَّ أَن قَالُوا أَخْرِجُوا آلَ لُوطٍ مِّن قَرْيَتِكُمْ إِنَّهُمْ أُنَاسٌ يَتَطَهَّرُونَ" (سورة النمل: 56)

“Ko si ohun kan ti ijo re fo ni esi tayo pe won wi pe: E le awon eniyan Luut jade kuro ninu ilu yin. Dajudaju won je eniyan kan ti won maa nforawon mo (nibi ese)” (Suurah Namulu: 56)

Olohun Oba soro nipa Anabi Isa

"وَقَوْلِهِمْ إِنَّا قَتَلْنَا الْمَسِيحَ عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ رَسُولَ اللّهِ وَمَا قَتَلُوهُ وَمَا صَلَبُوهُ وَلَكِن شُبِّهَ لَهُمْ وَإِنَّ الَّذِينَ اخْتَلَفُواْ فِيهِ لَفِي شَكٍّ مِّنْهُ مَا لَهُم بِهِ مِنْ عِلْمٍ إِلاَّ اتِّبَاعَ الظَّنِّ وَمَا قَتَلُوهُ يَقِينًا" (سورة النساء: 157)

“Ati pe oro enu won (yii): “Dajudaju awa pa Mosiih, ‘Isaa omo Moryam, Ojise Olohun.” Won ko si pa a, bee ni won ko kan an mo agbelebuu, sugbon A gbe awo re wo elomiiran fun won ni. Dajudaju awon ti won yapa enu nipa (eni ti won kan mo agbelebuu), kuku wa ninu iyemieji nipa re; ko si si imo kan kan fun won nipa re afi titele aroso. Dajudaj, won ko pa a”. (Suurah a-n-Nisaa: 157)

Olohun tun so nipa eni ti o keyin ninu awon Anabi Olohun ti i se Muhammad (Ki ike ati Ola Olohun maa ba):

"قَدْ نَعْلَمُ إِنَّهُ لَيَحْزُنُكَ الَّذِي يَقُولُونَ فَإِنَّهُمْ لاَ يُكَذِّبُونَكَ وَلَكِنَّ الظَّالِمِينَ بِآيَاتِ اللّهِ يَجْحَدُونَ" (سورة الأنعام: 33)

“A kuku ti mo pe ohun ti won n wi yoo ba o ninu je. Dajudaju won ko le pe o ni opuro, sugbon awon alabosi n tako awon aayah Olohun ni” (Suurah al- ‘Ani’aam: 33)

 

Siso afojusun to ga, ti a fe ki Musulumi maa sise to amuse re ni inu isemi re laye: Islam tila alakale afojusun Musulumi ni ile Aye yi, ohun naa ni wiwa ona a ti le ri iyonu Olohun ati Alujannah. Afojusun yi ko le je amuse ayafi eyin iku, Idi niyi ti e o fi maa ri pe musulumi n sise ijosin ni gbogbo igba kosi ni ko sisu, ko so pe o ti re oun, titi ti yoo fi ku. Nitori pe o ti mo pe afojusun oun yi, yio di mimuse lorun, Nipa bayi gbogbo igba ni o maa n ronu nipa aye yi, ati nipa awon isoro ile – aye, ati awon idaamu ibe lai banuje fun ohun ti o ba bo lowo re laye bikose pe o maa n kairoju nipa ohun ti o le mu sunmo Olohun, ti o si le je ki o ri Alujannah wo lorun. Sugbon awon ti kii se Olugbagbo ododo awon maa n se akolekan awon bi afojusun oore ile – aye, yio se je ti won, awon naa o si ri ipin kan ninu oriire pelu boseje pe awon naa n sise fun amuse re. Sugbon oriire won pari sibi amuse afojusun won laye. Leyinnaa kinni o kan leyiin ti won ba ti ri amuse afojusun won yii? Nigba kigba ti eniyan ba ti ri amuse afojusun re, onkan ti o ku fun ni asiko idaamu emi ati aibale okan fun eni ti ko ni (Iman) igbagbo. Irufe awon eniyan wonyi ni awon ti ko ni afojusun kan bikose pe amuse ojukokoro ati awon igbadun aye latari bi won yoo se bo ikun ati abe won yo. (Itumo aboyo ikun ati abe ni: Jije mimu lona Halaal ati Haraam pelu Zina sise)

Olohun ti bu won lori eyi. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ اللَّهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الأَنْهَارُ وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ" (سورة مـحمد: 12)

“Dajudaju Olohun yoo fi awon ti won gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Awon ti won si saigbagbo n gbadun, won si n je (kiri) gege bi awon eran – osin se n je (kiri). Ina si ni ibugbe fun won”. (Suurah Muhammod: 12)

Awon wonyi ti de ipo wi pe won ri awon afojusun won, won si ti di eni ti n se idije ni abala imo ijinle, ti awon nnkan wonyi ko ba ti won lo si ibi dida Olohun mo ati titele ase Re ko si oore Kankan nibe, beesi ni ko si anfaani Kankan nibe pelu Olohu ti Ola Re ga n royin isesi won bayii:

"أَمْ تَحْسَبُ أَنَّ أَكْثَرَهُمْ يَسْمَعُونَ أَوْ يَعْقِلُونَ إِنْ هُمْ إِلاَّ كَالأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ سَبِيلاً " (سورة الفرقان: 44)

“Tabi iwo n ro pe dajudaju opolopo won n gboran tabi pe won n se laakaye? Ki ni won nan, bi ko se bi agutan. Won wule sina ju lo”. (Suurah al-Furqoon: 44)

Mo wule woye si eni ti o parun, ki o fi wa beere wi pe bawo ni o se parun, bikose pe ki o woye si eni ti o la, ki o fi wa beere wi pe bawo ni o se la ti o si se yege. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَقَدْ ذَرَأْنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرًا مِّنَ الْجِنِّ وَالإِنسِ لَهُمْ قُلُوبٌ لاَّ يَفْقَهُونَ بِهَا وَلَهُمْ أَعْيُنٌ لاَّ يُبْصِرُونَ بِهَا وَلَهُمْ آذَانٌ لاَّ يَسْمَعُونَ بِهَا أُوْلَئِكَ كَالأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ أُوْلَئِكَ هُمُ الْغَافِلُونَ" (سورة الأعراف: 179)

“Dajudaju Ada opolopo eniyan ati alujannu fun ina jaanamo (nitori pe) won ni okan, Won ko si fi gbo agboye; won ni oju won ko si fi riran, won ni eti, wok o si fi gboran. Awon wonye dabi eran – osin. Won wule sonu julo. Awon wonye ni afonu – fora” (Suurah Aaroof: 179)

Oro yi ko tumo si riri aye sa ati gbigbe ise lati fi wa ije imu ju sile, ti yio fi wa dipe Musulumi o di eni ti yoo ma gbe ara le elomiran ki O too le rije rimu. Beesi ni Olohun ti Ola Re ga ti pa awon erusin re lase pe ki won o sise lori ile fun atile ri ije – imu, o si tun se eleyi ni okan ninu ohun ti ofin esin nwa lodo wa pe ki a se. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الأَرْضَ ذَلُولاً فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِن رِّزْقِهِ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ" (سورة الـملك: 15)

“Oun ni eni ti o ro ile fun yin Nitori naa, e rin ni awon agbegbe re, ki e si je ninu arisiki Re. Won yo si gbe eda dide si odo Re” (Suurah Mulku: 15)

Bi kose pe Islam ka ise sise lati wa igbadun aye kun ohun eyin lodo Olohun, nigbati o ba je pe afojusun re ni pe ki eniyan fi daduro lai gbarale elomiiran, ki awon ti o si pan dandan fun eniyan lati maa nawo fun naa ma fi maa toro jeun, bakannaa ki o si fi le maa ri owo na si ojuona rere, ki aaye ati ipo re lodo Olohun fi maa goke si. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ فِي سَبِيلِ اللّهِ ثُمَّ لاَ يُتْبِعُونَ مَا أَنفَقُواُ مَنًّا وَلاَ أَذًى لَّهُمْ أَجْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ وَلاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ" (سورة البقرة: 262)

“Awon ti n na owo won fun esin Olohun, ti won ko si fi iregun ati ipalara tele ohun ti won na, esan won n be fun won lodo Oluwa won, iberu ko ni si fun won, won ko si ni ri banuje”. (Suurah Al – Baqorah: 262)

Ohunkan ti a n fe ni ki o je ki aye wa lowo re ni, mase je ki aye wa lokan re. Ojise Olohun (Ti Ike ati Ola n be fun) so pe: “Owo ti o wa loke (Itumo ni pe: Owo ti n tore ti o si n se sara) lore ju owo ti o wa nisale lo, nipa bayi bere inawo re lati odo awon ti o pandandan fun o ki o nawo fun, sara ti O lore ju lo ni eyi ti a na fun awon ti O padandan fun wa ki a nawo fun tele. Eni ti o ba sora fun ki o ma maa se agbe ti n ko owo jo lati bi ise owo re, Olohun yo ran lowo, yoo si maa pese ije – imu fun nirorun”.

Eniti o o ba roro kuro nibi ki o maa toro lowo awon eniyan, Olohun yoo to o, pelu ki o ranlowo lati gbe oju kuro nibi agbe sise lodo awon eniyan.

Ki a gbero lati ni oore aaye fun afojusun ti a ni lori nina owo si ojuona rere je ohun ti won yoo san eniyan lesan lori e. ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so bayi pe: “Orisi eniyan merin ni aye wa fun, Erusin Olohun ti Olohun fun ni Owo ati Imo ti o wa n beru Olohun latari owo yi (Itumo eleyi ni pe: ki i na owo re sidi ese, bi kose pe o maa n jinna si gbogbo ohun ti ko ba dun mo Olohun ninu) o maa n fi woo re yi ro ebi po, O si mo wi pe Olohun naa ni eto kan ninu owo yi, Iru eni yi ni yoo wa ni ipo ti o ga julo. Bakanna, Erusin Olohun ti Olohun fun ni moo sugbon ti ko fun ni owo, ti o maa n so pelu okan ododo bayi pe: Ti o ba je pe mo ni owo lowo ni emi gan – an i ba maa na owo sojuona rere bi lagbaja se maa n se. Nipa bayi oun ti o ni erongba ododo ati eni to n nawo si ojona rere yi jo maa dogba ninu esan”. (Itumo ni pe, iru esan kannaa ni won yoo jo gba).

 

Dida Aye mo ni ti paapaa: Islam ti salaye fun Musulumi wi pe, Igbadun kan ni aye yi je. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ الشَّهَوَاتِ مِنَ النِّسَاء وَالْبَنِينَ وَالْقَنَاطِيرِ الْمُقَنطَرَةِ مِنَ الذَّهَبِ وَالْفِضَّةِ وَالْخَيْلِ الْمُسَوَّمَةِ وَالأَنْعَامِ وَالْحَرْثِ ذَلِكَ مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَاللّهُ عِندَهُ حُسْنُ الْمَآبِ" (سورة آل عمران: 14)

“Won se e ni oso fun awon eniyan inife igbadun lara awon obinrin ati awon owo wura ati fadaka regede ati awon esin ti won se ni oso ati awon eran osin (nnkan) o ko, iye ni nnkan igbaye gbadun odo Olohun si ni abo rere wa” (Suurah Aali Imroon: 14)

Islam si tun ti se alaye fun Musulumi bi aye se je ohun ti o kere to, bakannaa bi asiko ti eniyan maa lo laye naa tun se kere to. Olohun ti Ola Re gas so pe:

"اعْلَمُوا أَنَّمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ وَزِينَةٌ وَتَفَاخُرٌ بَيْنَكُمْ وَتَكَاثُرٌ فِي الأَمْوَالِ وَالأَوْلاَدِ كَمَثَلِ غَيْثٍ أَعْجَبَ الْكُفَّارَ نَبَاتُهُ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَاهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَكُونُ حُطَامًا وَفِي الآخِرَةِ عَذَابٌ شَدِيدٌ وَمَغْفِرَةٌ مِّنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٌ وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلاَّ مَتَاعُ الْغُرُورِ" (سورة الـحديد: 20)

“E mo pe dajudaju isemi aye yi je ere ati iranu, ati oso ati sise iyanran laaarin ara yin, ati wiwa opo dukia ati omo. O da gege bi ojo (ti o mu irugbin jade). Irugbin re si n jo awon alaigbagbo loju. Leyin naa, o maa gbe. Iwo yo si ri i ni pipon. Leyin naa, o maa di nnkan (ti ategun maa fe danu). Iya to le ati aforijin pelu iyonu lati odo Olohun si wa ni orun. Ki si ni, isemi aye yii bi ko se igbadun itannije”.

Islam si tun ti salaye fun Musulumi wi pe orun ni aaye ti yoo ti ri amuse afojusun paripari, gegebi Ojise Olohun (Ti ike ati Ola n be fun) ti so fun Umar Omo Khattab ni gba ti Umar se abewo Ojise Olohun, ti o si ba Ojise Olohun lori eni ti igi eni ti fa awon ila kan si legbe, Umar so pe: “iwo Ojise Olohun, ki ba si dara ki o lo ite, ti yio le ju eleyi lo! Ojise Olohun si dahun wi pe: Won o seto ki n maa ni igbadun aye fun mi, apejuwe emi ati aye ko je nnkankan bikose pe o dabi eni ti o gun ohunkan – igun, ti o waa sokale lati fi ese rin die losi abe igi ti o ni booji ni asiko eerun ti oorun mu pupo ni asiko ye, ti o kan lo wakati kan pere losan ojo ye nibe, leyin ti o sinmi wakati kan yi tan, o kuro nibe.” (Ahmad lo gba a wa).

Islam tun ti salaye fun Musulumi pe ile idaamu ati ile ti o le ko oriburuku ba eniyan ni aye je, tori pe ti o ba toro nigin ni ojo kan, yio tun fi aimoye ojo daru, ti o ba rerin die si eniyan, yio tun sunkun lopololpo pada. Koni maa toro lo gbere, Bikose pe didaru ati kiko idalaamu wa re lo po ju. Ile kan ti o n ko ori buruku ba eniyan ni fun eni ti ko ba daamo daradara, ti o si ti gba itanje pelu e, bakannaa ti o ti gbe ara le tan yan – an yan – an. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لَقَدْ خَلَقْنَا الإِنسَانَ فِي كَبَدٍ" (سورة الفجر:4)

“Dajudaju Awa ti da eniyan sinu isoro” (Suurah al – fajr: 4)

Ko leto fun eru ki o gbe ara le e, gegebi Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) se so nibi imoran re ti o gba omo Umar. O so pe: “Maa be ni aye, bii Ajoji tabi eni ti o fee fo ona soda” (Bukhari lo gba a wa).

Awon Oba ati awon arole nibi ipo ni won maa n lero pe awon n be ninu igbadun nla ati oriire. Gbgobo houn ti Abdul Rhaman Nasir ti o je okan lara awon Khaliffah Bani – Umayyah to gbajumo eniti o lo to aadota odun ati osu mefa lori ijoba. Eniti awon eniyan ro fun lati tele ase ijoba re. O je eni ti o gbajumo, o maa n ko ile nla nla, Aafin nla nla, ti o si ni ilapa pe o se ohun meremere laye. Leyin ti o ku, won ri ohun ti o fi owo ara a re ko sile bayi: Dajudaju gbogbo ojo aye ti o dun ti osi toro nini fun Khaliffah yi, ti awon Ojo yi o ni riru po kankana, ni Ojo bayi bayi ninu Osu bayi bayi, ninu odun bayi bayi, mo ka awon Ojo naa, mo ri wi pe gbogbo re je Ojo Merinla pere, Nipa bayi woye si eleyi ki o fi le mo pe gbogbo eniyan laye nbe ninu a i soriirire ati Wahala nla.

Nipa bayi, okan lara awon Akorin ti royin Aye leni ti o n se alaye pe isesi kan ki i lo gbere ni aye, ati pe adamo Aye ni Yiyipada ati ai le duro soju kan. O ni:

ILE AYE YI KO LE SEKU GBERE FUN ENIKANKAN KO SI LE JE PE ISESI YIO MAA LO GBERE.ILE AYE NI KI OJO KAN JE OJO IDUNNU FUN O KOMIIRAN JE OJO IBANJUE FUN O #

ENI TI IGBA KAN BA DUN NINU # AMOYE IGBA NI YIO TUN SE AIDA FUN PADA TOBA TUN YA.

Alfa wa Tiamiyy ni asiko ti n daro ipapoda ti o sele si omo re, oun naa salaye itumo Aye ni paapaa. O so pe:

Adamo ti a da mo o ni ki o maa lupo, Iwo ti o n gbe inu Aye iwo waa fee ki o maa toro nini, o wa la bo aye lorun ohun ti ki se adamo re, o fe ki o mo kuro ninu awon idoti ati lilupo, o dabi eni ti n wa ogunna ninu omi

Okan ninu awon Akorin salaye pe “Ohun ti iwo n pariwo pe o ko fe laye ni elomii o maa pariwo pe oun n fe”.

Gbogbo eni ti o ba pade ni o maa n kibosi igba re#

O ma se o!!! ile aye yi ti tani? Gbogbo igba ti Musulumi ba ti da eleyi mo, eyi yio je ki igbaradi re fun orun lekun si ni yio tun je ki o ma si Ajosepo Kankan laarin oun ati Aye, ati kiko emi le idekun re, eyi ti o maa n ye. Nipa bayi ko ni le banuje lori ohun ti o ba bo mo lowo ninu awon adun aye, tabi ki o banuje lori Adanwo kan ti o de ba a, bawo ni eniyan se fe maa banuje lori ohun ti O se pe bi o ba ye kuro lodo eni loni, yio ye lola. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"كُلُّ نَفْسٍ ذَآئِقَةُ الْمَوْتِ وَإِنَّمَا تُوَفَّوْنَ أُجُورَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فَمَن زُحْزِحَ عَنِ النَّارِ وَأُدْخِلَ الْجَنَّةَ فَقَدْ فَازَ وَما الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلاَّ مَتَاعُ الْغُرُورِ" (سورة آل عمران: 185)

“Emi kookan ni o maa to iku wo. A o si san yin ni esan yin ni ekunrere ni Ojo Ajinde. Nitori naa, enikeni ti A ba mu jinna tete si Inan, ti A si mu wo inu Ogba Idera, o kuku ti jere. Ki si ni igbesi aye tayo igbadun itanje” (Suurah aali – Imroon: 185)

 

pipase nipa nini (alabarin) ore rere ati jijinaa si awon alabarin buruku ati eni buruku. Ko si eni ti o le tako oripa ti nbe fun alabarin lara alabarin re, Won a maa so bayi ninu owe pe: (Ore maa n fa ore e re ni) Nipa bayi, ore re ati Alabarin – re ninu ki o fa e lo sibi daadaa tabi ki o fa e lo sibi aidara. Ninu ki o wo o tabi fa o lo sibi oriire tabi ori buruku, Ojise Olohun (ki Ike ati Ola Olohun maa be fun – un) ti se apejuwe bayi pe: “Apejuwe jijoko ti eniire ati jijoko ti eni buruku da gegebi eni ti O gbe lofinda Miski lowo ati eni ti n fe ina ewiri. Eni ti o gbe lofinda ninu ki O fun o lo ninu lofinda re tabi ki o ta fun e ninu re, ki o ri oorun ti o dara lati ibe. Sugbon eni ti n fe ategun si ewiri ninu ki o jo aso re ni ina tabi ki o maa gbo oorun elegbin” (Muttafak Alaei)

imaa joko ti eniire iranlowo nla loje fun o leyin iranlowo Olohun nipa diduro ti o lasiko isoro ati asiko ti awon adanwo ba de, yoo si je iyokuro fun o nibi ibanuje, nigba ti O ba n banuje, yiyo isoro kuro ni yoo tun je fun o nigbati o ba fe ki o ba o gbo bukata kan, ninu ohun ti yio maa fa ifokanbale ati isinmi ni yio je fun o, lati le dojuko awon isoro Ile Aye yi leyin Olohun, yatosi imaa joko ti eni buruku ti o maa je akoko eni ti o maa sa fun o, ti o maa yeperee re lasiko ti O nilo iranlowo re, ti yoo si maa bu o, ti eleyi o fi waa dakun inira, ibanuje ati ori buruku re si.

 

Pipase gbigbe ese jusile ati jijina si awon ese: awon ese maa nfa ori buruku fun eniyan ni, o si maa je idina lati de ibi oriire, yio mu eniyan lati ibi sisin Olohun lo sibi titele ife – inu (Ife – inu ni emi ti o maa n pa ase buburu) eyi ti o wopo si ni pe ti emi ko ba ti seri losi ibi Ododo, yo pada seri losi ibi ibaje. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"كَلاَّ بَلْ رَانَ عَلَى قُلُوبِهِم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ" (سورة المطففين: 14)

“Rara ko ri bee, amo ohun ti won n se nise (ibi) lo joba lori okan won”. (Suurah al – Mutofifiin: 14)

Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so pe: “Ti Olugbagbo ododo ba da ese kan, won yoo kan ekikan dudu kan si oka re, ti o ba ronupiwada, ti o si ja kuro nibi ese, ti o si toro aforijin Okan re yio di titunse, ti o ba lekun nibi ese dida, ekikan ye naa yio lekun si. Iye ni itumo “Roona” ti Olohun ti Ola Re ga so ninu tira Re:

"كَلاَّ بَلْ رَانَ عَلَى قُلُوبِهِم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ" (سورة المطففين: 14)

“Rara ko ri bee, amo ohun ti won n se nise (ibi) lo joba lori okan won.” (Suurah al – Mutofifiin: 14)

Saqroot so pe: Odaran elese maa n soriburuku ni gbogbo igba ni fun ese ti nda, tori pe eni ti o ba je elese, ti won o bawi lori ese to da oun ni yoo di oloriburuku julo ninu awon eniyan” bee ni yoo ma je ere ese ibawi to pamo ni gbogbo igba lori ese ti o se.

 

Rironu si awon ijo to lo ati wi woye si oro won pelu fifi oro ti won se isiti (Waasi)

Bee ni, bo ti wu ki aye o pe to, boti wu ki awon eniyan ibe o pe laye to, ibi titan naa ni yio gbeyin re tabi ki a pe ibi iparun ti yio sele latari ese awon eniyan ati abosi ti won n se naa ni yio pari re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"كُلُّ نَفْسٍ ذَآئِقَةُ الْمَوْتِ وَإِنَّمَا تُوَفَّوْنَ أُجُورَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فَمَن زُحْزِحَ عَنِ النَّارِ وَأُدْخِلَ الْجَنَّةَ فَقَدْ فَازَ وَما الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلاَّ مَتَاعُ الْغُرُورِ" (سورة آل عمران: 185)

“Emi kookan ni o maa to iku wo. A o si san yin ni esan yin ni ekunrere ni Ojo Ajinde. Nitori naa, enkeni ti A ba mu jinna tete si Ina, ti A si mu wo inu Ogba Idera, o kuku ti jere. igbesi aye ki se nkankan tayo igbadun itanje”. (Suurah aali-Imroon: 185)

Olohn ti Ola Re ga so pe:

"أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ كَانُوا أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَأَثَارُوا الأَرْضَ وَعَمَرُوهَا أَكْثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَاءتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ" (سورة الروم: 9)

“Se won ko rin ni ori ile ni, ki won wo bi atibotan awon ti won siwaju won ti ri? Won ni agbara ju won lo. Won fi ile dako. Won si lo ile fun ohun ti o po ju bi (awon ara Mokkah) se lo o. awon Ojise won mu awon alaye oro to yanju wa ba won. Nitori naa, Olohun ko se abosi si won, sugbon ori ara won ni won n se abosi fun”. (Suurah al-r-Ruum: 9)

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَعَادًا وَثَمُودَ وَقَد تَّبَيَّنَ لَكُم مِّن مَّسَاكِنِهِمْ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَكَانُوا مُسْتَبْصِرِينَ" (سورة العنكبوت: 38)

“(A tun ranse si awon) ara ‘Aad ati ara Thamuud. (Iparun won) si kuku ti foju han kedere si yin ninu awon ibugbe won. Esu se awon ise won ni oso fun won. O si se won lori kuro ninu esin (Olohun) won si ka ara won kun Oluriran (nipa oro aye)” (Suurah al – Ankabuut 38).

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَكَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ بَطِرَتْ مَعِيشَتَهَا فَتِلْكَ مَسَاكِنُهُمْ لَمْ تُسْكَن مِّن بَعْدِهِمْ إِلاَّ قَلِيلاً وَكُنَّا نَحْنُ الْوَارِثِينَ" (سورة القصص: 58)

“Meloo meloo ninu ilu ti A ti pare, ti won yo ayopora aye – jije ninu ilu naa. Iwon yi ni awon ibugbe won, ti A ko je ki eni kan kan gbe ibe leyin won afi (fun asiko) die. Awa si ni A n jogun won”. (Suurah al – Qosos: 58)

Ti Musulumi ba mo wi pe aye ati gbogbo ohun ti o wa laye ni yio tan, yoo le yonu si idajo Olohun, yoo le gba fun Olohun, nipa bayi yoo le ni isinmi, yoo si le maa wa isinmi fun awon elomiran. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَأَنذِرِ النَّاسَ يَوْمَ يَأْتِيهِمُ الْعَذَابُ فَيَقُولُ الَّذِينَ ظَلَمُواْ رَبَّنَا أَخِّرْنَا إِلَى أَجَلٍ قَرِيبٍ نُّجِبْ دَعْوَتَكَ وَنَتَّبِعِ الرُّسُلَ أَوَلَمْ تَكُونُواْ أَقْسَمْتُم مِّن قَبْلُ مَا لَكُم مِّن زَوَالٍ * وَسَكَنتُمْ فِي مَسَاكِنِ الَّذِينَ ظَلَمُواْ أَنفُسَهُمْ وَتَبَيَّنَ لَكُمْ كَيْفَ فَعَلْنَا بِهِمْ وَضَرَبْنَا لَكُمُ الأَمْثَالَ*" ( سورة إبراهيم: 44 – 45)

“Kilo fun awon eniyan nipa ojo ti iya yoo de ba won, ti awon ti won sabosi yo si wi pe: “Oluwa wa, lo wa lara fun asiko die si i, a maa jepe Re, a si maa tele awon Ojise” Se eyin ko ti bura siwaju pe eyin ko nii kuro nile aye ni? * e si semi ni aye awon ti won se abosi fun ara won, o si han si yin bi A ti se fun won, A si fi apejuwe lele fun yin”. (Suurah Ibroohim: 44 – 45)

 

Mimaa wo eni ti ko to ni ninu oore aye: Dajudaju omoniyan le maa semi ninu idekun ati oore, ti yoo maa yi ninu oore, ti o si n mo pe oore nla wa fun oun, sugbon eni ti yoo mo ni oore ni eni ti ko ni iru re. ti o ba ni owo kan lowo ti o si ni bukata pupo lati gbo, ranti pe elomiran n be ti oun ko ti e ni nnkankan lowo. Ti o ba je alaisan, ti o si ni agbara lati maa lo maa bo, ranti pe elomiran ti o je alaisan ti ko le maa lo maa bo wa, ti o ba je pe omo kansoso lo bi, ti o nwa alekun, ranti pe elomiran n be ti o ti pinnu lati na gbogbo owo ti o ni, ki o fi di eni ti won o ma pe ni “Baba lagbaja”o. Ojise Olohun (ki ike ati Ola o maa ba a) so pe: “E maa wo eni ti ko to yin, e mase maa wo eni ti o ju yin lo, tori pe, sise bee ni o dara ju, ti e o fi ni fojukere Oore Olohun to se fun yin” (apanupo bukhariy ati muslim)

Ti o ba wo eni ti ko to o nibi Oore aye, Okan re yio bale, wa si le mo Oore ati Ola ti Olohun da o, Bakannaa yio je ki o mo pe awon kan n be ti won toro ki awon da bi iwo. Okunrin kibosi ifunpinpin isemi ti o n be fun lo sodo Yunus omo Ubaid, Yunus ba so fun pe: Se o dun mo o ninu ki o gba egberun lona Ogorun, Dir’ham lati fi paaro oju re? okunrin yi ni: Rara o! o tun bi i leere wi pe. O da fi owo sile ki o gba egberun lona ogorun Dir’ham paaro owo re? okunrin yi tun ni: Rara o! o tun bi pe: Ese re n ko, ki o si gba egberun lona ogroun Dir’ham dipo? Okunrin yi tun dahun pe: Rara O! leyinnaa o waa ranti awon idekun ti Olohun se fun – un, leyinnna (Yunus) so fun pe: Mo ri o leni ti won fi aimoye egberun ta lore, sibesibe o tun kibosi pe bukata re ko ti i biya!!! Sugbon ti o ba je oro igbaradi fun ati le ri Oore torun ni, maa wo eni ti o ga ju o lo, ki o fi le baa mo ibi ti o ti se aseeto ati aseju, Idi ni pe ipele ipele ni Alujannah ati ipo odo Olohun, ma ni afokante wiwo Aljunnah Kankan, bikose Aljunnah Firidaos, eleyi ti o ga julo.

 

Ayo okan: Eleyi ni iroro okan ati iyonu si kadara Olohun ati kiko fun emi re nibi Oore owo awon eniyan ati gbigbafa fun ero Olohun. Gbogbo eko ti Al – Qur’an gbe wa ati Anabi (TI IKE ATI OLA N BE FUN) lo ni ilapa nla nibi gbigbin ayookan si igbaaya awon Musulumi, eleyi ko ri be bikose pe nitori ki won o le lo isemi onifokanbale eleyi ti o maa gbe won jinna si Ole jija, keeta, Ikorira ara eni, eleyi ti O se pe aini ayookan maa n fa yiyonu si Oore eyi ti Olohun ba pin fun eru. Eleyi si je ohun ti a le ri. Tori pe eni ti o ni ayookan loni ifokanbale julo ninu awon eniyan, oun si ni isemi re dara julo pelu. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تَمُدَّنَّ عَيْنَيْكَ إِلَى مَا مَتَّعْنَا بِهِ أَزْوَاجًا مِّنْهُمْ زَهْرَةَ الْحَيَاةِ الدُّنيَا لِنَفْتِنَهُمْ فِيهِ وَرِزْقُ رَبِّكَ خَيْرٌ وَأَبْقَى" (سورة طه:131)

“Ma se feju re si ohun ti A fi se igbadun fun won ni nnkan orisirisi ti o je yodoyindin aye yi. (A fun won) nitori ki A le fi se adanwo fun won. Ese Oluwa re dara ju lo. O si maa wa titi laelae” (Suurah Tooha: 131)

Ojise Olohun (Ki ike ati Ola Olohun maa ba a) so pe: “O ti jere, eni naa ti o ba je pe o gbafa fun Olohun, o si je eni ti Arisiki re to fun – un, bakannaa ti Olohun si fun ni ayookan lori oore ti Olohun se fun”. (Muslim lo gba a wa).

Nitori pe ninu awon adamo ominiyan ni ninife aye ati imaa wa ona lati le ko oore aye jo, gegebi bi ojuse Olohun (ki Ike ati Ola maa be fun) ti fun wa ni iro nipa eyi, ninu oro re bayi pe: Bi omoniyan ba ni ogba meji ti o kun fun owo, yoo tun maa wa iketa ni. Kosi nnkan to le kun ikun omo Adamo ayafi erupe, (Itumo eleyi ni pe, ko si ohun ti o le to omo Anabi Adamo ayafi iku). Olohun a maa samojukuro, asi maa fi eni ti o ba seri kuro nibi ese se konge lile tele ase Olohun.

Nbe ninu awon idanileko Anabi, awon ilapa nla lori botise je pe Musulumi gbodo se aye ni kekere, ki o si ni ayookan pelu Oore aye die ti Olohun ba fun – un, Ojise Olohun (Ki Ike ati Ola maa baa) so pe: “Enikeni ti o ba ji leni ti emi re bale, ti o ni alaaafia ara, ti ounje ti yoo je ni ojo ye si n be lodo re, oro re ti dabi eni ti o se pe a ti ko gbogbo Oore aye jo fun”.

Bi eniyan ba ronu, yoo ripe awon nnkan ti Ojise Olohun (Ki ike ati Ola Olohun ba) so yi ni ohun ti omoniyan nilo ni ojumo ojo kan, sugbon nipa ola ti o je ojo keji, Olohun nikan loni imo iye, tori pe, o ko mo boya o maa semi laye di ola abi bee ko. Tori pe O ko mo akosile to wa ninu ayanmo re, boya o maa seku laye di ola ni abi ko tile ri bee. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ اللَّهَ عِندَهُ عِلْمُ السَّاعَةِ وَيُنَزِّلُ الْغَيْثَ وَيَعْلَمُ مَا فِي الأَرْحَامِ وَمَا تَدْرِي نَفْسٌ مَّاذَا تَكْسِبُ غَدًا وَمَا تَدْرِي نَفْسٌ بِأَيِّ أَرْضٍ تَمُوتُ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ" (سورة لقمان: 34)

“Dajudaju Olohun odo Re ni imo nipa Akoko (opin aye) wa. O n so ojo kale. O mo ohunkohun ti n be ninu apoduke. Emi kan ko si mo ohun ti o maa se nise ni ola. Emi kan ko si mo ile wo ni o maa ku si. Dajudaju Olohun ni Onimimo, Olumo ikoko” (Suurah Luqmoon: 34)

 

Gbigba fun ase Olohun ati gbigbe ara le Olohun: Olohun ni Oludari oro eda Re, eni ti o maa n fun eni ti o ba wu ni oore, ti o si maa n ko Oore fun eni ti o ba wu. Eni ti o maa n gbe eni ti o ba wu ga, eni ti o maa n re eni ti o ba wu sile, Oun ni o maa n pin ije imu ti o si maa n fi ranse si eni ti o fee fun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلِ اللَّهُمَّ مَالِكَ الْمُلْكِ تُؤْتِي الْمُلْكَ مَن تَشَاء وَتَنزِعُ الْمُلْكَ مِمَّن تَشَاء وَتُعِزُّ مَن تَشَاء وَتُذِلُّ مَن تَشَاء بِيَدِكَ الْخَيْرُ إِنَّكَ عَلَىَ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ" (سورة آل عمران: 26)

“So pe: Olohun; Olukapa ijoba, iwo ni o n fi ijoba fun eni ti o ba fe. Iwo si ni on n gba ijoba lowo eni ti o ba fe. Iwo ni o n buyi fun eni ti o ba fe. Iwo si ni o n tabuku eni ti o ba fe. Owo Re ni Oore wa. Dajudaju iwo ni Alagbara lori gbogbo nnnkan” (Suurah aali – Imron: 26)

Ti eniyan ba mo pe won ti pebubu Arisiki won si ti pin – in lati igba ti omoniyan ti wa ninu iya re, gegebi Ojise Olohun (Ki Ike ati Ola Olohun maa ba a) se fun wa ni iro pelu oro re yi, koye ki omoniyan maa se wahala pupo mo.

“Dajudaju won ko eda enikookan yin jo ninu iya re fun ogoji ojo ni ipo ato, leyinnaa ni ipo eje kiki fun iru asiko ye, bakannaa, leyinaa ni ipo eran ekiri kan, fun iru asiko ye bakannaa. Leyinnaa won ran Malaika kan si i, lati fe emi si lara, won si pa a lase lati ko awon nnkan merin kan sile fun – un (eda tuntun yi), awon ohun ti o maa kosile naa ni. Arisiki re, Igba ti o maa lo laye, Ise ti o maa se laye, Nje yoo je olori buruku ni abi oloriire, mo fi Olohun ti ko si iru Re bura, “Dajudaju enikookan yin yoo maa se ise omo Alujannah lo titi ti yio fi ku bii deede igunpa kan laarin oun ati iku, ti akosile yii si maa gba iwaju re, ti yoo si pari ise re pelu ise omo ina, ti yoo si wo ina naa, Bakannaa, omoniyan o maa se ise omo ina titi ti yio fi ku bii deede igunpa kan laarin oun ati iku, ti akosile yii si maa gba iwaju re, ti yoo si pari ise re pelu ise omo Alujanna, ti yoo si wo Alujannah naa”. Bukhari lo gba a wa.

Dajudjau gbogbo eniyan ni yoo gba ohun ti Olohun ba ko fun – un ni aye yi, yala Arisiki tabi isemi, yoo ni ifokanbale yoo si le yonu si i. Ojise Olohun (ti Ike ati Ola nbe fun) so pe: “Dajudaju Jibril (ki Alaafia Olohun maa ba a) ti ju nnkan kan si okan ati emi mi (Itumo eleyi ni pe won ti fi ranse si mi) wi pe: Emi kan ko le ku laelae titi ti igba ti a kosile fun – un yio fi pe, ti Arisiki ti a bu fun naa yio si pe, Nipa bayi, e beru Olohun, ki esi wa Arisiki yin lonan ti o dara, e ma jeki pipe orisiki yin soyin di eni ti yoo maa wai sibi iyapa Ase Olohun, dajudaju won o le ri ore Olohun ayafi pelu titele ase Re”.

 

Yiyonu si ohun ti Olohun pin fun ni: Aima maa binu si idajo Olohun to fi de ori awon oro ti eniyan o le sojukokori si. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ لاَ يَحِلُّ لَكُمْ أَن تَرِثُواْ النِّسَاء كَرْهًا وَلاَ تَعْضُلُوهُنَّ لِتَذْهَبُواْ بِبَعْضِ مَا آتَيْتُمُوهُنَّ إِلاَّ أَن يَأْتِينَ بِفَاحِشَةٍ مُّبَيِّنَةٍ وَعَاشِرُوهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ فَإِن كَرِهْتُمُوهُنَّ فَعَسَى أَن تَكْرَهُواْ شَيْئًا وَيَجْعَلَ اللّهُ فِيهِ خَيْرًا كَثِيرًا "{النساء/19}

“Eyin ti e gbagbo ni ododo! ko letoo fun yin ki e jogun awon Obinrin ni tipatipa, Ko si letoo fun yin) lati da won lagara. (ti Obinrin yoo fi so pe oun ko se mo) ki e fi le gba apa kan ohun ti e fun won, ayafi ti won ba huwa ibaje ponbele. E ba won lo pelu daadaa. Ti e ba korira won o le je pe e korira kinni kan, ki Olohun si fi opolopo oore sinu re”. (Suura a – an Nisaa: 19)

Nigbamiran Oore le je ohun ti okan re ko, ki abura si je ohun ti okan re fe, ti iwo o si ni i mo.

Olohun Oba ti Ola Re ga so pe:

وَعَسَى أَن تَكْرَهُواْ شَيْئاً وَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ وَعَسَى أَن تُحِبُّواْ شَيْئاً وَهُوَ شَرٌّ لَّكُمْ وَاللّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لاَ تَعْلَمُونَ " (البقرة: 216)"

“O si le je pe e korira kini kan, ki ohun naa si je Oore fun yin O si tun le je pe e nifee si kini kan. Ki Ohun naa si je aburu fun yin Olohun nimo. Eyin ko si nimo”. (Suurah Al – Baqorah 216)

 

imo papa itumo jiju ara eni lo larin awon eniyan nibi gbogbo nnkan: jiju ara eni lo wa ninu ilanan ti Olohun tila kale laye yi, eleyi ti omoniyan ko ni agbara lati yii pada, nigba ti Musulumi ba ti mo wi pe jiju ara eni lo yi larin awon eniyan, Olohun nikan si ni o mo idi naa, eleyi o je ki o le dunnu, ki o si fi okan bale, ki emi re si pa sofo kuro nibi keeta ati adisokan buruku si eni ti o ju lo ninu Ola. Olohun so pe:

"وَاللّهُ فَضَّلَ بَعْضَكُمْ عَلَى بَعْضٍ فِي الْرِّزْقِ فَمَا الَّذِينَ فُضِّلُواْ بِرَآدِّي رِزْقِهِمْ عَلَى مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَهُمْ فِيهِ سَوَاء أَفَبِنِعْمَةِ اللّهِ يَجْحَدُونَ" {النحل/71}

“Olohun lo se ajulo fun apa kan yin lori apa kan ninu arisiki. Awon ti A fun ni ajulo won ko ni agbara lati fun awon eru won ni arisiki won, ti won o si jo pin in ni dogba dogba Nitori naa, se idera Olohun ni won yoo maa tako?” (Suurah – an – Nahl 71)

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"انظُرْ كَيْفَ فَضَّلْنَا بَعْضَهُمْ عَلَى بَعْضٍ وَلَلآخِرَةُ أَكْبَرُ دَرَجَاتٍ وَأَكْبَرُ تَفْضِيلاً" {الإسراء/21}

“Wo bi A se fun apa kan won lore ajulo lori apa kan (nile aye). Dajudaju torun tun tobi ju lo ni ipo, o si tobi ju lo lore ajulo” (Al – Isroo 21)

 

A I ni maa tanmo iru Oore aye kan ti o wa lodo elomiran, ati wiwoye si awon Oore owo won yi, nigba ti o ba je pe tori aye ni tanmo yi fi waye:

Olohun ti Ola Re ga so pe:

" قُلْ إِنَّ رَبِّي يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ لَهُ وَمَا أَنفَقْتُم مِّن شَيْءٍ فَهُوَ يُخْلِفُهُ وَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ" )سبأ: 39)

“So pe: Dajudaju Oluwa mi, o n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n di won (re fun elomiran). Ati pe ohun kohun ti eyin ba na ni o maa fi (omiran) paaro re, Oun ni o lore ju lo ninu awon olupese” (Suurah saba: 39)

Nigbati o je pe itanmo nini je okan lara ohun ti o maa n kodi ayookan, kiko ara ro fun rirankan Oore aye ti O wa lodo elomiran si ti di ohun ti idanileko ti wa lori i re fun awon Muslumi, eleyi ri bee ki Musulumi fi le gbe aye onifokanbale.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تَتَمَنَّوْاْ مَا فَضَّلَ اللّهُ بِهِ بَعْضَكُمْ عَلَى بَعْضٍ لِّلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِّمَّا اكْتَسَبُواْ وَلِلنِّسَاء نَصِيبٌ مِّمَّا اكْتَسَبْنَ وَاسْأَلُواْ اللّهَ مِن فَضْلِهِ إِنَّ اللّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا" {النساء/32}

“E ma se rankan ohun Olohun fi soore ajulo fun apa kan yin lori a pa kan, Ipin (esan) n be fun awon okunrin nipa ohun ti won se nise, ipin (esan) si n be fun awon obinrin ni pa ohun ti won se nise, Ki e si toro ni odo Olohun alekun Oore Re, dajudjau Olohun n je Olumo nipa gbogbo nnkan”. (Suurah a – ni – Nisaa: 32)

Nipa bayi Islam ti fi ki Musulumi woye si ara a re, ki o si se isiro emi ara a re bakannna ki o gbe ohun ti o ba yato si eyi ju nsile paaro fun ki o wa je pe irankan ati mimaa wo Oore aye ti o wa lodo elomiran, ki o fi waa maa se ojukokoro Oore aye yi lemi. Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Onilaakaye Ojogbon ni eni ti o ti n se isiro emi re siwaju ki won o to ba siro re lojo Igbende, ti o si n se ise ni igbaradi fun isemi ti o kan leyin iku, Eni ti o kagara ni eni ti n tele ife inu re, ti o sin tanmo nkan dada lodoOlohun”

 

imaa wa isora fun keeta, owu jije lona aidaa, Adisokan buruku ati Ole jija. Awon aisan wonyi lewu pupo fun omoniyan, won si maa n le oriire jinna si eniyan, o si maa n fa ori buruku, eni ti ko ba yo ayookan pelu ohun ti Olohun ba pin fun – un yoo garun wo Oore ti Olohun se fun elomiran, eleyi yoo si fa lo sibi keeta, sise eleyi ti O tun le fa adisokan buruku, Ole jija, eyi ti o si maa n ti eniyan lo sibi ibawi ati ijiya nla, onikeeta, aladisokan buruku maa ko iparun ba ara a re, yoo si ko emi ara a re si wahala ko to kan eni ti oun se keeta re.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَمْ يَحْسُدُونَ النَّاسَ عَلَى مَا آتَاهُمُ اللّهُ مِن فَضْلِهِ فَقَدْ آتَيْنَآ آلَ إِبْرَاهِيمَ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَآتَيْنَاهُم مُّلْكًا عَظِيمًا" {النساء/54}

“Abi won n se ilara awon eniyan lori ohun ti Olohun fun won ninu Oore ajulo Re ni? Dajudaju A fun awon ara (Anabi) Ibrahim ni Tira ati Oye esin (Sunnah). A si fun won ni ijoba to tobi”. (Suurah a – n – Nisaa: 54)

Abajade keeta si ni motomoto, bakannaa ohun si ni akoko ese ti won koko se Olohun. Olohun ti Ola Re ga so iroyin nipa Iblis (esu) o se moto moto, o si ko lati teriba niti Keeta. Olohun ti Ola Re ga so pe:

" قَالَ أَرَأَيْتَكَ هَـذَا الَّذِي كَرَّمْتَ عَلَيَّ لَئِنْ أَخَّرْتَنِ إِلَى يَوْمِ الْقِيَامَةِ لأَحْتَنِكَنَّ ذُرِّيَّتَهُ إَلاَّ قَلِيلاً " ( الإسراء: 62)

“O wi pe: O fee ri eyi ti o ponle ju mi lo yii? Dajudaju ti Iwo ba fi le lo mi lara di Ojo Ajinde. Dajudaju emi yoo ko iparun baa won aromodomo re afi awon die” (Suurah Isroo 62)

Ojise Olohun (ki Ike ati Ola Olohun maa be fun – un) so bayi lati se idanileko fun awon ijo re lati mu won jinnna si awon aisan to lewu yi, ti o maa n kodi oriire “E ma maa se keeta, e ma maa sabosi ki Oloja fi le gbe owo le oja fun eni ti o fee ra oja, e maa maa korira ara a yin, e ma maa deyin ko ara a yin, ki eni Kankan ma maa taja lori oja elomiran, e maa je erunsin Olohun ni ti omo – iya kan naa, omo – iya ni Musulumi kan si ekeji, ko gbodo se abosi ekeji re, Iberu Olohun ibi yi lo wa (O toka si igbaaya re leemeta) o to ni abuuru fun omoniyan ki o maa yepere omo iya re keji, gbogbo Musulumi kookan si omo iya re Musulumi loje, eewo ni fun ki o ta eje re sile, tabi ki O ji owo tabi dukia re, tabi ki o ba omooluabi re je”. (Muslim lo gba a wa).

Ki Islam le baa wa itoju si awon aisan to lewu wonyi, ki o si fi le se Musulumi ni ojukokoro ki o maa fe daada fun elomiran ni idanileko se wa latinu Al – Qur’aan alaponle fun Musulumi pe ki o maa tanmo – on daada fun awon omo iya re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَالَّذِينَ جَاؤُوا مِن بَعْدِهِمْ يَقُولُونَ رَبَّنَا اغْفِرْ لَنَا وَلإِخْوَانِنَا الَّذِينَ سَبَقُونَا بِالإِيمَانِ وَلاَ تَجْعَلْ فِي قُلُوبِنَا غِلاً لِّلَّذِينَ آمَنُوا رَبَّنَا إِنَّكَ رَؤُوفٌ رَّحِيمٌ" {الحشر/10}

“Awon ti won de leyin won n so pe: Oluwa wa, Foriji awa ati awon omo iya wa ti won ti siwaju wa ninu igbagbo ododo. Ma se je ki adisokan buruku wa ninu okan wa si awon ti won gbagbo ni ododo, Oluwa wa, dajudaju iwo ni Alaanu Onikee”. (Suurah al – Asr: 10)

Ki o je ki itanmo – on daada si awon omo – iya re je ohun ti o wa latinu okan ododo, ki o si je ki awon omo iya re maa ni ipin ninu adura re ti yoo maa se fun won. Ojise Olohun (ti ike ati ola n be fun) so pe: “Eniti o ba se adua fun omo – iya re adua yi, yoo so pe (Amin) ki iru re naa maa je ti e”. (Muslim lo gba a wa)

 

Gbigbe motomoto ati okan giga si awon eniyan ju sile: Eni ti o je oni motomoto ko le je Oloriire, awon eniyan o si maa yepere re fun okan giga tiwon ri lara re, ati iyepere awon eto won ti o wa fun – un, oun naa yoo korira awon eniyan, awon eniyan naa o si korira re. kinni ero re pelu iru isemi bayi na. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللَّهِ بِغَيْرِ سُلْطَانٍ أَتَاهُمْ كَبُرَ مَقْتًا عِندَ اللَّهِ وَعِندَ الَّذِينَ آمَنُوا كَذَلِكَ يَطْبَعُ اللَّهُ عَلَى كُلِّ قَلْبِ مُتَكَبِّرٍ جَبَّارٍ" {غافر/35}

“Awon ti n jiyan nipa awon aayah Olohun laisi eri kan ti o de ba won, ese nla ni ni odo Olohun ati ni Odo awon ti won gbagbo ni Ododo, Baye ni Olohun se n fi edidi bo gbogbo okan onigbeeraga, ajeninipa” (Suurah Ghoofri: 35)

Ojise Olohun (ki ike Olohun ati Ola Re maa ba a) sope: “Eni ti o ba ni deede horo oka baba ninu motomoto lokan, koni wo Aljannah, Nipa bayi, Okunrin ba beeru pe: Iwo Ojise Olohun, eniyan a maa fe ki aso oun dara, ki o dan loju, ki bata re naa re wa, O dahun pe: Dajudaju oba to rewa ni Olohun, O si feran ohun ti o ba rewa. Motomoto ni titako ododo pelu mimaa yepere awon eniyan”. (Muslim lo gba a wa).

 

Kiko fun ni nipa Ahun sise: Nitori pe eleyi maa n mu oriire lo, o si maa n fa ori buruku wa. Nitori pe Ahun maa n be ninu idaamu a ti so owo re, bakannaa ati ipaya lori re, nipa bayi ojukokoro ti o lekan yi maa kofun nibi ko’gbadun owo re ati ki o le na si awon oju ona rere. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ يَحْسَبَنَّ الَّذِينَ يَبْخَلُونَ بِمَا آتَاهُمُ اللّهُ مِن فَضْلِهِ هُوَ خَيْرًا لَّهُمْ بَلْ هُوَ شَرٌّ لَّهُمْ سَيُطَوَّقُونَ مَا بَخِلُواْ بِهِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَلِلّهِ مِيرَاثُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَاللّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ" {آل عمران/180}

“Ki awon ti n sahun pelu ohun ti Olohun fun won ninu Oore ajule Re ma se lero pe Oore ni fun won. Rara, aburu ni fun won. A o fi ohun ti won fi nsahun de won lorun ni Ojo Ajinde. Ti Olohun si ni ogun awon sanmo ati ile, Olohun ni Olumo – ikoko ohun ti e n se nise” (Suurah aali – imroon: 180)

Ahun yio maa yeju fun awon eniyan nitori bi won se korira re ati bi awon eniyan ko se gba ti e, bakannaa bi oun naa se korira awon eniyan ki won ma le gba ninu Oore odo re. idi niye ti Islam fi se Musulumi lojukoro a ti maa nawo fun awon eniyan ati aima maa se ahun, Islam si salaye pe Ahun sise, ati mimaa pawo mo owo, ati ki a ma maa nawo sojuona ti ofin esin fe ki a nawo si, maa n fa ki oro lo mo eniyan lowo. Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Ko si ojumo kan ti o mo ba awon erusin Olohun laye ayafi ki awon malaika meji kan maa sokale lati sanmo, okan ninu awon mejeeji maa n se adua pe: Olohun maa ba wa se iropo adipele fun nawonawo. Ekeji si maa n so pe: Olohun maa ba wa se iparun fun Ahun ti kii nawo”. (Bukhari lo gba a wa).

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) ti salaye awon nnkan ti o maa n gbeyin aisan Ahunsise ninu awon aburu ati oriburuku. Ojise Olohun (ti ike ati Ola Olohun n be fun) so pe: “E beru abosi sise, tori pe abosi sise okunkun ni lojo Igbende, e si tun beru Ahunsise, e ri Ahunsise yi, ni O ko iparun ba awon to siwaju yin, ohun lo gbewon lo sisbi ki won o maa ta eje ara a won sile, ti won fi wa n se ohun eto leewo fun ara a won”. (Eberu abosi tumo si, e wa isora nibi kiko sinu abosi).

Nitori ki Islam le so iroyi yi di ikorira lemi Musulumi lo fi so di ara awon iroyin abuku, ti o maa n fa adinku igbagbo lemi eni ti o ba ni iru iroyin yi. Ojise Olohun (ti ike ati ola n be fun) so pe: “Eruku ti o wo inu ikun erusin Olohun kan lojuona Olohun ati eefin ina Jahanamo kole kojo papo laelae sinu ikun iru erusin Olohun naa Bakannaaa, Ahunsise ati igbagbo ko le kojopo sinu okan erusin Olohun laelae” (Sunnah Nissah ati Sohih Jamiu: 7616)

 

imaa se suuru pelu yiyonu si Idajo Olohun: Ai ma maa banjuje, ati ai ma maa binu lori gbogbo ohun ti o ba sele si Musulumi. Suuru sise se dandan lati fi kora ninu isemi Aye teletele ki o to o tun dipe o je oranyan ninu esin, nitori pe eniyan ko le ri amuse erongba re ayafi pelu suuru. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ اصْبِرُواْ وَصَابِرُواْ وَرَابِطُواْ وَاتَّقُواْ اللّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ" {آل عمران/200}

“Eyin ti e gbagbo ni ododo e maa se suuru, e maa parowa suuru, e maa fowo sowopo, ki e si maa beru Olohun nitori ki e le jere”. (Suura aali – Imroon: 200)

Atipe totori pe Aye yi Ile Adanwo ni, a je pe suuru wa ninu ohun ti o se dandan ki a fi kora, Gege bi Olohun Olutoju wa, Oba ti Ola Re ga se so ninu oro Re pe:

"وَلَنَبْلُوَنَّكُمْ بِشَيْءٍ مِّنَ الْخَوفِ وَالْجُوعِ وَنَقْصٍ مِّنَ الأَمَوَالِ وَالأنفُسِ وَالثَّمَرَاتِ وَبَشِّرِ الصَّابِرِينَ" {البقرة/155}

“Dajudaju A o maa dan yin wo pelu kini kan latara ipaya ati ebi ati adunku ninu awon dukia, awon emi ati awon eso, Ki o si fun awon onisuuru ni iro idunnu” (Suurah al – Baqrooh: 155)

Siseni lojukokoro suuru sise de ori imaa se aforijin ati amujukuro fun eni ti o ba se asise nipa kikolu eto re, ti o tun waa se aida si o, iye ri bee ki o fi le maa fo emi mo kuro nibi ote ati ikorira. Olohun ti Ola Re so pe:

" وَلَمَن صَبَرَ وَغَفَرَ إِنَّ ذَلِكَ لَمِنْ عَزْمِ الْأُمُورِ" (الشورى: 43)

“Enikeni ti o ba se suuru ti o tun se aforijin, dajudaju iye wa ninu awon nnkan ti o soro (lati se)” (Suurah a-s-suuro: 43)

Ki suuru le je nnkan ti gbogbo Musulumi won o ma wa ti won o si maa se igbyanju fun, ni Olohun fi se ife Re ni ohun ti yio maa be fun awon onissuru. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَاللّهُ يُحِبُّ الصَّابِرِينَ" {آل عمران/146}

“Olohun si nifee awon onisuuru” (Suurah aai – imroon: 146)

Olohun ti se adehun fun eni ti o ba ni iroyin suuru yi lara wi pe esan ti o po ti ko ni i ja nigba Kankan nbe fun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّمَا يُوَفَّى الصَّابِرُونَ أَجْرَهُم بِغَيْرِ حِسَابٍ" {الزمر/10}

“A o pee san awon onisuuru fun won lai ni isiro” (Suurah a - s – zumor: 10)

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Olohun ko se oore to dara tosi gbaayi fun enikankan ti o to oore suuuru”. (Bukhariy ati Muslim lo gba a wa).

Islam si ti salaye wipe leyin ti eniyan ba se suuru lori Ifunpinpin, Yiyokuro ninu inira lo maa n tele e. bakan naa, leyin suuru ti eniyan ba se lori ibanuje kan ayo ati idunu lo ma n gbeyin re, gbgobo igba si ni isesi yi maa n lo bee, Olohun so pe:

"إنَّ مَعَ الْعُسْرِ يُسْرًا" (سورة الشرح:6)

“Dajudaju idekun wa leyin iniran”. (Suurah A – s – serii: 6)

Okan lara awon akorin n so iroyin isesi re lasiko ile – koko bayi pe: Nkan le koko lasiko kan, nigbati mo gba fun amuwa Olohun Moba yo kuro ninu isoro yi, bee si ni mo lero pe eniyan ko ni le yo kuro nibe tele.

Suuru sise pin si ona meta:

Akoko: Suuru sise lori titele ase olohun: Olohun ti Ola Re ga so pe:

"سَلاَمٌ عَلَيْكُم بِمَا صَبَرْتُمْ فَنِعْمَ عُقْبَى الدَّارِ" {الرعد/24}

“(won o so pe): Alaafia fun yin nitori ifarada yin, Ogba idera si dara ni ikangun” (suurah ar-Ra’d: 24)

Eleekeji: sururu sise nipa jijinna si awon nnkan, ti emi maa sojukokoro re ti o maa n gbadun mo emi ti o si je nnkan eewo. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَاصْبِرْ نَفْسَكَ مَعَ الَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُم بِالْغَدَاةِ وَالْعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُ وَلاَ تَعْدُ عَيْنَاكَ عَنْهُمْ تُرِيدُ زِينَةَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَلاَ تُطِعْ مَنْ أَغْفَلْنَا قَلْبَهُ عَن ذِكْرِنَا وَاتَّبَعَ هَوَاهُ وَكَانَ أَمْرُهُ فُرُطًا" {الكهف/28}

“Wa pelu awon ti n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale, ma se gboju re mejeeji kuro ni odo won lati wa oso isemi aye (yii), Ma se tele eni ti A ti so okan renu nibi iranti wa ti o si tele ife – inu re, oro re si di radarada”. (Suurah al – khaf: 28)

Eleketa: Suuru sise lori (kadara) Ayanmo: Olohun ti Ola Re ga so pe:

"مَا أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ إِلاَّ بِإِذْنِ اللَّهِ وَمَن يُؤْمِن بِاللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ" {التغابن/11}

“Adanwo kan ko le sele ayafi pelu iyonda Olohun, Enikeni ti o ba gba Olohun gbo ni ododo, Olohun maa fi ona otito mo okan re (pe adanwo kan ko seyin kadara), Olohun si ni Olumo nipa gbogbo nnkan”. (Suurah a-t- Tagoobun: 11)

Islam ti to Musulumi sona lati maa se suuru lori idajo Olohun ati kadara pelu pe ki o maa so ohun ti Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) salaye fun, ki o fi le jinna si ibinu Olohun ati ibanuje, ki o si fi le maa si ilekun fun ofo ati abamo “Ojise Olohun (TI IKE ATI OLA N BE FUN) sope: “kosi enikan ti adanwo kan yoo kan ti yoo so pe: “Odo Re ni a ti wa, Odo Re si ni a o pada si” Inna Lilahi wa inna ilei roojihuun” Olohun la mi nibi adanwo to de ba mi, ki o si ba mi fi Oore gbeyin re” ayafi ki Olohun la eni nan ninu adanwo to de ba a, ki o si fi Oore gbeyin re fun”. (Muslim lo gba a wa)

 

Gbigbe ibinu ju sile ati ki eniyan ma se maa kanra: Idini pe, Ibinu maa n gbe eniyan lo si ibi ti eniyan a ti di eni eebu, ti o si tun di eni ti yoo se abamo ni gbogbo aye re, nipa bayi ti won yoo fi wa dina oriire mo eniyan, ti yiio fi wa gbe eniyan ju sinu idaamu. Olohun ti Ola Re ga ti se eyin fun eni ti O ba ni iroyin yi lara. Olohun so pe:

" وَالَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ وَإِذَا مَا غَضِبُوا هُمْ يَغْفِرُونَ " (الشورى: 37)

“Ohun ti o wa ni odo Olohu tun wa fun) awon ti n jinna si awon ese nla nla nigba ti won ba binu won n se aforiji” (Suurah a – si – suuro: 37)

Eniti o ba kappa lati bori ibinu re, iru eni yi ti ni ikapa lati le se atemora gbogbo isoro aye. Ojise Olohun (ti iike ati ola n be fun) so pe: “Ki i se Alagbara ni eni ti o da enikeji mole nibi ijakadi, bikose pe Alagbara ni eni ti o kapa emi re lasiko ibinu”. (Bukhariy).

Eni ti o ba kappa emi re, yoo da oriire to wa nibe mo, nitori pe o ti ri papa Aranse lori emi ti o le gbe loo se ohun ti yio so di alabuku nigbeyin.

 

Sise ojukokoro si imaa se amojukuro nibi aida. Iwa yi je ohun ti emi maa n fe laarin awon eniyan ara won. O si maa nmu adisokan buruku si ara eni kuro lokan, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِينَ يُنفِقُونَ فِي السَّرَّاء وَالضَّرَّاء وَالْكَاظِمِينَ الْغَيْظَ وَالْعَافِينَ عَنِ النَّاسِ وَاللّهُ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ" )عمران/134}

“Awon ti n na owo won nigba idera ati nigba inira, awon ti n ko ibinu won ni ijanu, awon alamojuukuro fun awon eniyan nibi asise, Olohun nifee awon oluse reree” (Suurah al – imron: 134)

Koda Islam tun pase fun ohun ti o tun ga ju gbogbo eleyi lo, nkan naa ni, ki a maa fi daadaa pade aida, ki a fi le de ipo riri isegun lori emi, nipa bayi emi yio di mimo kuro nibi egbin ikorira ara eni, oriire yio waa kari, bakannaa ni mimu araa wa lomo iya. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تَسْتَوِي الْحَسَنَةُ وَلاَ السَّيِّئَةُ ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ فَإِذَا الَّذِي بَيْنَكَ وَبَيْنَهُ عَدَاوَةٌ كَأَنَّهُ وَلِيٌّ حَمِيمٌ" {فصلت/34}

“(Iwa( rere ati (Iwa) buruku ko dogba. Fi eyi ti o je iwa rere to dara ju lo ti aburu lo, Nigba naa, eni ti ota wa laaarin iwo ati e maa di bi ore olasun – unmo pekipeki” (Suurah Fussilat: 34)

 

Dida aba daada ati ijinan si aba aburu: Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Kosi fifi eye da aba aburu, dipo eleyi, ohun ti o dara ju eleyi lo ni “Al – faalu”. Won beere pe: Kinni itumo “Alfaalu” Iwo Ojise Olohun? O dahun pe: aba rere ti yio maa wu enikookan yin lati gbo”. ( Bukhariy lo gba a wa).

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) o je awokose fun gbogbo Musulumi, o si je eni ti “Al faalu” ( aba daada) maa n wu lori, o si maa n korira “At – tashaumu” (aba buruku) (Bukhariy).

Al – faalu: Eyi ni oro rere ti eniyan maa n fe lati gbo.

At – tashaumu: Eyi ni oro ti o tumo si aba buruku.

 

Kiko fun ara eni lati maa da aba – buruku ati mi maa topinpin omo lakeji: Eni ti o ba maa n da aba buruku isemi – ibanuje, aini ifidimule si ibikan, fun iberu ti yio wa fun – un, ati idaamu mimaa so aida awon eniyan kakiri, eni ti o ba n to pinpin awon eniyan, yoo di eni ikorira, ijinnasi lodo awon eniyan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيرًا مِّنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ وَلاَ تَجَسَّسُوا وَلاَ يَغْتَب بَّعْضُكُم بَعْضًا أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَن يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتًا فَكَرِهْتُمُوهُ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَّحِيمٌ {الحجرات/12}

“Eyin ti e gba gbo ni ododo e jinna si opolop erokero, Dajudaju apa kan erokero je ese, e o si gbodo maa soro ara yin leyin, se okan ninu yin nifee sipe ki o maa je eran – ara omo iya re to ti ku? Eyin korira re. e paya Olohun, Dajudaju Olohun ni Olugba ironupiwada, Onike”. (Suurah al – Hujuroot 12)

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “O dowoyin lati maa daba, tori pe abadida je oro iro to ga, e si ma maa topinpin awon eniya lati le mo asiri won, e si maa maa korira ara a yin, e ma maa deyin ko ara a yin, pelu bi ba ara a yin ja, e maa je erusin Olohun ni ti jije omo – iya, ki enikankan si ma ba iyawo ti elomiran ti ba so oro ife tele soro ife titi ti eni akoko yoo fi fee gegebi iyawo, tabi ki o ko o sile lati fe e, e si mase fe obinrin kan ati omo iya baba re tabi oun ati omo iya iya re lasiko kan naa, obirnin kan ko si gbodo gba aawe lasiko ti oko re wa ni ile ayafi ki o je pelu ase oko re lo fi gba a". (Aawe asegbore ni a n so o), ko si gbodo yonda ki enikan kan wo ile oko re lasiko ti oko re wanile ayafi pelu iyonda oko re, ohunkohun ti o ba fi se sara ninu ohun ti oko re ba fun – un, ilaji esan ni yoo ri nibe. Obinrin kosi gbodo beere fun Ikosile obinrin miran kio le gba aye re, ki won le so di iyawo, nipa bayi, ki o gba pe ohun ti Olohun kosile fun oun ni yio je ti ti e.” (Baeaqy)

 

imaa wo ohun ti o wa pelu eni lowolowo, gbigbe ironu nipa ohun ti a n wo niwaju jusile ati gbi gbagbe ohun ti o ti lo: Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَن تَقُولَ نَفْسٌ يَا حَسْرَتَى علَى مَا فَرَّطتُ فِي جَنبِ اللَّهِ وَإِن كُنتُ لَمِنَ السَّاخِرِينَ {الزمر/56} أَوْ تَقُولَ لَوْ أَنَّ اللَّهَ هَدَانِي لَكُنتُ مِنَ الْمُتَّقِينَ {الزمر/57} أَوْ تَقُولَ حِينَ تَرَى الْعَذَابَ لَوْ أَنَّ لِي كَرَّةً فَأَكُونَ مِنَ الْمُحْسِنِينَ" {الزمر/56-58}

“Nitori ki emi kan ma baa wi pe yee, o ma se fun mi!!! nhbi ijafara mi lori ai teel ase Olohun Ati pee mo wa ninu awon ti n fi (oro Re) se yeye* Tabi ki o m,a baa wi pe: Ti o baje pe Olohun fi ona nmo mi ni, dajudaju emi iba wa ninu awon olupaya (Olohun) * Tabi nigba ti o ba ri iya (inan) ki o ma baa wipe: Ti o ba je pe ipadasaye wa fun mi ni, emi iba si wa ninu awon oluse – rere” (Suurah Zamor 56 – 58)           

okan lara awon ojogbon aye atijo so pe: (Ohun ti o ba ti bo, o ti ku (Itumo eleyi ni pe: Ohun ti o ba ti lo ti lo naa, ma wule ronu nipa re mo) Eyi ti o si n ro, o pamo fun o (itumo re ni pe: O je ohun ti o ko mo, tori pe o wa ni ojo iwaju) ti e si ni asiko ti o wa nibe lowolowo. Idi eleyi ni pe, imaa ronu nipa ohun to ti koja kole da ohun toti bo pada laelae, bakannaa, imaa ronu nipa ojo iwaju, yi o je ki o male mojuto ise eyi to wa lowo bayi, nipa bayi, gbe ara le, eyi ti o wa pelu e lowolowo.

 

Sise ojukokoro sibi maa tore ati imaa nawo: Dajudaju nibi ki a mo tore ni Oriire wa, ko si nibi ki a maa gba ore, (gift). Iwo naa beere lowo ara a re, leyin ti O ba se daadaa kan, bii ki O fun eni ti ebi n pa lounje, tabi ki o gbe inira kan kuro fun eni ti n je irora, ati bee bee lo (nibi awon ise rere). “Iwo emi yi, kinni o n ri nibi daadaaa sise?” Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ يَأْتَلِ أُوْلُوا الْفَضْلِ مِنكُمْ وَالسَّعَةِ أَن يُؤْتُوا أُوْلِي الْقُرْبَى وَالْمَسَاكِينَ وَالْمُهَاجِرِينَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلْيَعْفُوا وَلْيَصْفَحُوا أَلاَ تُحِبُّونَ أَن يَغْفِرَ اللَّهُ لَكُمْ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ" {النور/22}

“ki awon ti won ni Ola ati igba laaye ninu yin ma se bura pe awon ko nii se daadaa si awon ibatan, awon alaini ati awon ti won gbe ilu won ju sile nitori esiin Olohun. Ki won se amojukuro (fun won), ki won ma se fiya je won, se eyin naa ko fe ki Olohun forijin yin ni? Olohun si ni Alaforijin, Onikee” (Suurah Nur: 22)

sugbon Islam kilo fun wa pe ki a ma fi iregun tele ore ti a ba ta eniyan, tabi inawo kan ti a ba se fun eniyan, tori pe eleyi yio ba laada je, yio si mu oriire lo kuro fun iru eni yi, eleyi si ni yio je ki olore le maa tu oju ka. Olohun ti Ola Re ga so pe:

" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ لاَ تُبْطِلُواْ صَدَقَاتِكُم بِالْمَنِّ وَالأذَى كَالَّذِي يُنفِقُ مَالَهُ رِئَاء النَّاسِ وَلاَ يُؤْمِنُ بِاللّهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ فَمَثَلُهُ كَمَثَلِ صَفْوَانٍ عَلَيْهِ تُرَابٌ فَأَصَابَهُ وَابِلٌ فَتَرَكَهُ صَلْداً لاَّ يَقْدِرُونَ عَلَى شَيْءٍ مِّمَّا كَسَبُواْ وَاللّهُ لاَ يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ " )البقرة: 264)

“Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se fi iregun ati ipalara ba awon ore yin je, bi eni ti n na owo re ni ti sekarimi, ko si ni igbagbo ninu Olohun ati Ojo Ikehin. Apejuwe re da bi apejuwe apata kan ti erupe n be lori re. Bi Ojo nla se ro si i, o si ko erupe kuro lori re patapata. Won ko ni agbara lati jere Kankan lori ohun ti won se nise. Olohun ko sin ii fi ona mo ijo alaigbagbo”. (Suurah Baqorah: 264)

Ti o ko ba ni ohun ti o maa na, o dowo re lati maa so oro itunu, bakannaa ki o si maa tujuka, eleyi gan – an lore ju inawo ti iregun gbeyin re lo. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قَوْلٌ مَّعْرُوفٌ وَمَغْفِرَةٌ خَيْرٌ مِّن صَدَقَةٍ يَتْبَعُهَآ أَذًى وَاللّهُ غَنِيٌّ حَلِيمٌ" {البقرة/263}

“Oro rere ati aforijin dara ju ore ti ipalara te le lo, Olohun ni Oloro, Alafarada” (Suura al – Baqorah: 263)

Nipa bayi ohun ti o leto fun Musulumi ni ki o maa je olore nibi gbogbo nnkan, fun a tile samulo awon eko Pataki ti esin re ko. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَالَّذِينَ تَبَوَّؤُوا الدَّارَ وَالإِيمَانَ مِن قَبْلِهِمْ يُحِبُّونَ مَنْ هَاجَرَ إِلَيْهِمْ وَلاَ يَجِدُونَ فِي صُدُورِهِمْ حَاجَةً مِّمَّا أُوتُوا وَيُؤْثِرُونَ عَلَى أَنفُسِهِمْ وَلَوْ كَانَ بِهِمْ خَصَاصَةٌ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفْسِهِ فَأُوْلَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ" {الحشر/9}

“Awon ti won n gbe ninu Ilu Modinah siwaju won, ti won si ni igbagbo ododo, won nifee awon ti won fi ilu mokkah sile wa si odo won (ilu modinah) won ko si ni (keeta) kini kan ninu igba – aya won nipa nnkan ti won fun won, won si nfe won ju emi ara won lo koda ki o je pe awon naa ni bukata gan – an si (ohun ti won fun won). Enikeni ti A ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonye ni awon olujere” (Suurah al – Hashr: 9)

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Mo pe iwo Yaziid omo Asad, n je o nife si ki o wo Alujanna? Mo dahun pe: “Beeni”. Ojise Olohun so pe: Maa ri wi pe ohun ti o fe fun ara a re ni o n fe fun omo iya re Musulumi”.

  1. Nina imoran fun awon eniyan: Iye ni imaa to awon eniyan sonan lo sibi daadaa sise, ki a si tun maa ko fun won kuro nibi aburu sise, nitori ki won o le maa lo isemi oloriire. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلْتَكُن مِّنكُمْ أُمَّةٌ يَدْعُونَ إِلَى الْخَيْرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَأُوْلَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ" {آل عمران/104}

“Ki o maa be ninu yin, ijo kan ti o maa pe (awon eniyan) si ibi ise rere, Won o si maa pase sise daadaa, Won o si maa ko sise aidaa, Awon wonye si ni olujere” (Suurah Al – imroon: 104)

  1. Nina owo fun awon ti iya owo n je, ti won je Alaini, ati imaa tore lona to dara si ibi to dara: Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَالَّذِينَ صَبَرُواْ ابْتِغَاء وَجْهِ رَبِّهِمْ وَأَقَامُواْ الصَّلاَةَ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرًّا وَعَلاَنِيَةً وَيَدْرَؤُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ أُوْلَئِكَ لَهُمْ عُقْبَى الدَّارِ" {الرعد/22}

“awon to se suuru lati fi wa oju rere Oluwa won, Won n kirun won n na ninu ohun ti A pese fun won ni ikoko ati ni gbangba, won si n firere ti aburu lo, Awon wonye ni atubotan ile rere n be fun”. (Suurah ar – Ra’d: 22)

  1. Ninan iyi eni lati maa fi ba awon eniyan sipe tabi kun won lowo lonan to dara, ki o fi le je pe bukata awon eniyan yio maa biya: Olohun ti Ola Re ga so pe:

"مَّن يَشْفَعْ شَفَاعَةً حَسَنَةً يَكُن لَّهُ نَصِيبٌ مِّنْهَا وَمَن يَشْفَعْ شَفَاعَةً سَيِّئَةً يَكُن لَّهُ كِفْلٌ مِّنْهَا وَكَانَ اللّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ مُّقِيتًا" {النساء/85}

“Enikeni ti O ba se ikunlowo ni ikunlowo daada, o maa ri esan ninu re, enikeni ti o ba si se ikunlowo ni ikunlowo aburu, O maa ri ipin ese ninu re, Olohun si je Oluso lori gbogbo nnkan” (Suurah a-n-Nissa: 85)

Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) maa n so bayi ni igbakigba ti onibere ba wa ba tabi won n fe ki o waa ba awon gbo bukata kan: “E kun ara a yin lowo, won o san yin ni esan nla lori i re”. (Sohih Bukhariy)

  1. imaa na daada sise ati iwa rere fun awon eniyan lonan orisirisi: Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so pe:

“Eni ti Olohun feran ju ninu awon eniyan ni eni ti o n se awon eniyan lanfaani ju lo, bakannaa ise ti Olohun feran ju lo ni Idunnu kan ti O gbe wo inu Musulumi tabi ibanuje kan ti o ka kuro fun – un, tabi o ba san gbese orun re, tabi o ba le ebi lo, tori pe ki n tele omo – iya mi Musulumi kan lati ranlowo lori bibiya bukata je ohun ti mo nife si ju ki n se atipo (itikaaf) ni Mosalasi fun osu kan lo, Eni ti o ba ko ibinu re duro, Olohun yoo ba da aso bo ihooho re lati bo lasiiri, eni ti o ba gbe ibinu mi, koda ki O je pe ohun ti o wu ni ki o tu ibinu naa sile, Olohun yoo ti tori eleyi ba fi idunnu kun okan re remuremu lojo Igbende, eni ti o ba fi ese re rin tele omo – iya re lati fi le ri bukaata re biya, titi ti o fi ri i biya, Olohun ti Ola Re ga yoo ba oun naa fi ese re rinle lojo ti aimoye ese ba n ye kuro lojuona, bakannaa dajudaju iwa buruku maa n ba ise rere je, gegebi omi eso-inanbi se maa n ba oyin je”. (Tobarani lo gba a wa. Al – Albaani si sope o ni alaafia).

Gbogbo eleyi naa wa lara ki a maa fe daadaa fun elomiran, bi imona Islam se maa de odo awon miiran ki won fi le ri oriire iru eyi ti Musulumi n ri, ki won si tun fi le ri isinmi, iru eyi ti Musulumi n ri, ati pe ki imona Islam fi le yo won kuro ninu aigbagbo eleyi ti o le fawon wo inan. E je ki a wo okan lara awon sahabe (ki Olohun ba ni yonu si i). nigbati Oba Ruum bi leere idi ti won fi wa si ilu re, o dahun pe: A wa lati waa yo awon erusin Olohun kuro nibi imaa sin eda lo sibi imma sin Oba Adeda, ati lati le kuro nibi ifunpinpin isemi Aye lo sibi igbaaye ike ti torun, ati lati kuro nibi abosi awon esin yoku, losi ibi deede eyi ti Islam gbe wa.

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Olugbagbo ododo ti o ni akolekan ijosin ati itele ase Olohun lore lodo Olohun ju Olugbagbo ododo ti o je ole lo, Sugbon ekini keji naa ni O lore ninu: Nipa bayi, Maa sojukokoro nnkan ti yio se o lanfaani, ki o si maa fi Olohun se alatileyin, ki o si mase kagara lori eyi, Ti Adanwo kan ba de ba o, Ma maa so pe: to ba je pe mo ti se nnkan bayi bayi ni, Adawo yi ki ba ti ba mi, sugbon maa so pe: Olohun ti kadara gbogbo nnkan, ohun ti O ba si fe ni yio sele, tori pe gbolohun ti o ba ni oro “to ba je wipe” o maa n si lekun ise Esu sile ni”. (Sohih Muslim).

Itumo “maa sojukokoro nnkan ti yio se o lanfaani” ni pe sojukokoro titele ase Olohun ati sise ojukokoro oore odo Olohun.

Itumo “Ma se kagara" ni pe ma se roju si titele ase Olohun ati wiwa iranlowo Olohun.

 

ORIGUN KERIN: Igbagbo ninu awon Ojise Olohun

Awon naa ni awokose ti a o maa wo fi kose, ko rorun lati da Olohun mo, bakannaa ko rorun lati de ibi ojulowo oriire ayafi ki a to ojuona awon Ojise Olohun.

Idi niye, ti Ibn Qoyyim (ki Olohun ba ni ke) se so ninu tira Zaadul Ma’aad (Idi karun, ojuewe keje) bayi pe: “E ri oogun aisan okan ni, gbigba fa fun awon Ojise Olohun (ki ike Olohun ati Ola re maa je ti won) ko si onan ti eniyan fi le de ibi oogun aisan okan ayafi ona odo won, Tori pe atunse okan maa n waye pelu ki O je okan ti o mo Olohun re ti o je Eleda re, ati pelu mimo oruko re, awon iroyin Re, ati awon ise Re, ati mimo awon idajo re. bakannaa ki o si je okan to n wa iyonu Olohun ati ife Re ti o si maa jinna si awon nnkan ti Olohun ko fe, ati awon nnkan ti o le bi Olohun ninu, Okan ko si le ni alaafia, ko si tun le maa semi ayafi pelu iye, Kosi si ona lati ri eyi, ayafi ona odo awon Ojise Olohun, Eniyan ko le de ibi alaafia okan laisi titele awon Ojise, onan miran ti a ba gba lati fun awon emi ni alaafia yato si onan awon ojise Olohun onan asise ni, okan gbodo jinna si ife – inu re, Eni ti ko ba le se iyato laarin ekinni keji (ohun ti yio mu ki emi le je aaye tabi oku) yi, Irufe eni bee ti wa ninu awon oku, irufe eni bee si ti teri sinu awon ibudo to sokunkun”.

 

ORIGUN KARUN: Igbagbo ninu Ojo Ikeyin

Nigbati omoniyan bati ni igbagbo ninu Ojo Ikehin, Igbende ati esan lori ise, isiro ise, okan re yio bale emi re yio si ni isinmi, nitoripe O mo amodaju pe eyikeyi ohun ti won ba gba lowo re laye yi, won yoo ba gba pada lorun, ati pe eni ti o ba se abosi re tabi o koja aala si, won yoo ba gba esan pada, sugbon ki i se pelu onan ti won gba se abosi fun laye, bikose pe pelu gbigba ninu ise ere tabi fifi kun ese.

Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so bayi fun awon Sahabe pe: “Nje e mo taani (muflisu)? Won dahun pe: (Al – Muflisu) ninu wa naa ni, eni ti koni Dirham kan, ti kosi ni dukia Aye Kankan. Nipa bayi Ojise Olohun (Ki Ike Olohun ati Ola maa ba) so pe: Al – Muflis ninu ijo mi, ni eni ti o de lojo Igbende, pelu Irun, ati Zakat, ati Aawe, ti ode leni ti o ti bu lagbaja laye, o ti pa iro zina sise mo eleyi, o ti ta eje eleyi naa sile lona aito, O ti lu eleyi, won wa yo ninu ise rere re fun eni eleyi, ati fun eni toun, ati eni tiyin, ti ise rere re ba waa tan ko to dipe won ba tan oran ti o da tan yan – n yan, won o ba tun maa mu ninu ese awon ti ose laye, won yoo ma da papa mo ti e, leyinnna won o taari re lo sinu inan”. (Sohih Muslim).

Ki a le mo bi deede Olohun (ti mimo je ti E) ti se to, Idajo yi ko mo lori awon ede abara nikan, O wa lori gbogbo eda Olohun ni. Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so pe: “Dajudaju won o da eto onikaluku pada fun – un, titi de ori eran osin ti ko ni iwo, ti won o ba gba esan lowo eran osin ti o ni iwo, fun kikan ti o kan eyi ti ko ni iwo laye.” (Ibn Hibaan lo gba a wa).

Lopin igba ti o ba ti ni igbagbo ninu ojo ikehin, yoo mo pe gbigbo nnkan ti o ba bo mo lowo laye yi gege bi apeere bii ki eniyan ma ni Alaafia tabi owo, tabi oro, gbogbo oore yi ni yoo pada ni debi wi pe yio tun po koja ohun ti O lero ninu oye re lo, ti o ba ti wo Alujannah. Olohun ti Ola Re ga so nipa awon idekun ti O ti pese sile fun awon Olugbagbo Ododo ni Alujannah bayi pe:

"فَلاَ تَعْلَمُ نَفْسٌ مَّا أُخْفِيَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعْيُنٍ جَزَاء بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ" {السجدة/17}

“Ko si emi kan ti o mo ohun ti A fi pamo fun won niu awon nnkan itutu oju. (O je) esan ohun ti won n se nise (rere)” (Suurah a-s-Sajdah: 17)

Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so pe: “Olohun ti Ola Re so pe: Mo ti pese Oore ti oju kori ri, ti eti ko gbo ri, ti okan eda abara kan ko lero re ri, nipa bayi e maa ka Ayat yi ti e ba fe:

"فَلاَ تَعْلَمُ نَفْسٌ مَّا أُخْفِيَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعْيُنٍ جَزَاء بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ" {السجدة/17}

“Ko si emi kan ti o mo ohun ti A fi pamo fun won ninu awon nnkan itutu oju. (O je) esan ohun ti won n se nise (rere)” (Suurah a-s-Sajdah: 17) (Bukhariy lo gba a wa)

Ko le baa je pe gbogbo adanwo ati gbogbo idaamu ati isoro ti Musulumi ba pade laye maa fuye loju re ni o fa ki Ojise Olohun (ti Ike Olohun ati Ola re n be fun) fi salaye pe gbogbo iya to je eniya laye patapata ni eniyan o gbagbe ti o ba ti wo Alujannah, Ojise Olohun (ti Ike ati Ola n be fun) so pe: “Won o mu eni ti o gbadun ju laye lo inu ina lojo Igbende, won o ju sinu ina leekan pere won o tun yo jade pada, leyinnaa won o bi leere pe: Iwo Omo Adam, nje o ri Oore kan peepee bi ninu Isemi ri? Nje ike kan gba odo re koja ri? Yoo, dahun pe: Rara o, oun fi Olohun bura, oun kori Ooore ri. Won o tun mu eni ti o je alaini julo laye wonu Alujannah, won o ju sinu Alujnnah leekan pere, won o tun yo o jade, leyinnaa won o bi leere pe: iwo Omo Adam, n je o ri iya aini Oore ri bi? Nje inira kan ti e gba odo re koja ri bi? Yoo dahun pe: Rara o, oun fi Olohun bura, Inira aini ko gba odo oun koja ri, oun kosi ri inira Kankan ri”. (Muslim lo gba a wa).

Nigba ti Musulumi bati mo eleyi, Aye yoo rorun fun – un, yoo si di eni ti yoo jinna tefetefe si fifi suta kan enikeji re tabi jije eto won mole lonan abosi, bikose pe yoo tun gbe gbogbo ohun ti o ba jo iwa abosi ju sile fun iberu ki o ma fi ko sibe, Igbagbo yi, yio maa da aabo bo o, ko fi le je pe yoo ma le se gbogbo ohun ti yoo fi la ni Ojo Igbende ti igbagbo yi yio tun je ko jinna si sise abosi fun elomiran.

 

ORIGUN KEFA: Igbagbo ninu idajo Olohun ati Kadara yala eyi ti o dara tabi eyi ti o buru

oun ni mimo wi pe: ohun ti o ba bani, ko le foni ru, ohun ti o si foni ru kole kanni, Eni ti o ba gba Olohun gbo, o di dandan fun ki o gba idajo Olohun ati kadara Re, bakannaa ki o si yonu si ohun ti Olohun ba pin fun – un. Olohun ti Ola Re ga so pe:

" مَا أَصَابَ مِنْ مُصِيبَةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي أَنْفُسِكُمْ إِلَّا فِي كِتَابٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ نَبْرَأَهَا إِنَّ ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ (22) لِكَيْلَا تَأْسَوْا عَلَى مَا فَاتَكُمْ وَلَا تَفْرَحُوا بِمَا آتَاكُمْ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ (23) " (الحديد 22-23)

“adanwo kan kan ko ni sele ni ori ile tabi (eyi ti o sele si emi yin) ayafi ki o ti wa ni akoole ki A to seda re, dajudaju iye rorun fun Olohun lati se, nitori ki e ma se maa banuje lori ohun ti o ba bo fun yin, ati nitori ki e ma se maa yo ayoju lori ohun ti O ba fun yin, Olohun ko si nife si gbogbo onigbeeraga, onifaari”. (al hadeed: 22-23)

Ojise Olohn (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “so ofin Olohun, Olohun naa yoo so o, so ofin Olohun, O maa ri Olohun ni iwaju re, da Olohun mo lasiko irorun, Oun naa yoo da o mo lasiko inira, ti o ba fee beere Oore Olohun ni ki o maa bi, Ti o ba n wa atileyin lori nnkan kan, Olohun ni ki o mu ni alatileyin. Gege ikowe ti pari ise lori kiko gbogbo ohun ti yio sele, ti awon eniyan ba gbiyanju lati se o lanfaani pelu ohun ti Olohun o ko, won kole ni agbara lati le se bee, Bi gbogbo awon eniyan ba si tun gbiyanju lati fi ara ni o, pelu ohun ti Olohun ko ko, won kole ni agbara lati se bee. ti o ba ni agbara lati se ise pelu suuru ati amodaju, se bee, ti O ko ba si ni agbara, a je wi pe, ki o se suuru, tori pe suuru sise lori ohun ti emi eniyan ko fe je ohun ti o ni oore pupo, ki o si loo mo pe aranse n be pelu suuru sise, ki o si tun mo wipe yiyo kuro ninu isoro maa n be pelu ibanuje, ki o si tun mo wi pe irorun maa n be pelu inira ni”. (Tirimidhi lo gba a wa).

Nipa bayi, Igbagbo ninu idajo Olohun ati kadara maa n mu eniyan jogun iyonu Olohun, o si maa n mu ni de ipo isinmi emi, ati ifokanbale okan, eleyi ti o maa n gbe eniyan de ipo idunnu, ati ipo ai ri ibanuje, Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so bayi pe: “Olugbagbo ododo ti o ni agbara lore lodo Olohun, o si tun je eni ti Olohun nife si pupo ju Olugbagbo Ododo ti o je ole lo, ore nbe fun iknni-keji won, maa se ojukokoro si ohun ti yio se o lanfaani, ki o si maa fi Olohun se Alatileyin re, ki o si ma sole, ti adanwo kan ba si de ba o, ma maa so pe, kani mo ti se bayi bayi ni, adanwo yi ko ba ti sele o. sugbon maa so pe Olohun ti kadara, ohun ti Olohun ba fe si ni yio sele, tori pe siso gbolohun “kani kani” lo maa n silekun ise Esu”. (Muslim lo gba a wa).

Itumo eleyi ni pe: Ma maa banuje lori ohun ti o ti bo, ki O si maa wo iwaju, ki o gbe imaa wo eyin ju sile, ti a ba ronu si opoplopo awon aisan to fonka si aarin awon eniyan lorile aye loni, a o ri wi pe eyi ti o po nibe loje abajade ibanuje pelu aisi ifokanbale, eleyi ti o si tun je ohun ti o fa ibanjue naa tun ni a i ri awon nkan ti O nwu emi eni. Nipa bayi, pelu igbagbo ododo ninu idajo Olohun ati kadara ni o le fi bori awon ibanuje re, awon aibale okan, ati awon isoro pelu iyonda ase Olohun, Eyi si tun ni yio je ki o le maa woye si ojo iwaju, ti O file maa sise lati le ri oore ojo iwaju, ti o si fi le gbe ohun to ti koja lo ju sile bakannaa ti o si gbagbe ohun ti o ti koja lo, pelu ki O si ma maa tun banuje lori ohun ti o ti lo. Ti a ba si tun woye si omoniyan loni, a o ripe iburu re ati ipaya re je okan ninu awon nkan ti islam ti fi ogun si, bi:

1. IBERU NIPA IJE IMU (ARISIKI): Itumo eleyi ni gbogbo ohun ti eniyan fi le gbe isemi ro, ti o je pe laisi re yoo ku. bi ohun jije, tabi ohun mimu. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَفِي السَّمَاء رِزْقُكُمْ وَمَا تُوعَدُونَ" {الذاريات/22}

“Arisiki yin ati ohun ti A n se ni adehun fun yin wa ni sanmo” (Suurah Thaariyat: 22)

Ododo ni oro Olohun ti o tobi, Ije – imu eniyan a ti sanmo lo ti n wa, Idi ni pe awon ojo ti n sokale lati sanmo ni omoniyan fi n semi, Ojo yio mu irugbin hu, Omoniyan yoo si maa mu omi, bakanna, sanmo ni gbogbo ohun ti won sadekun pe yio je isemi Aljannah gbere tabi isemi ina gbere tun wa. Olohun ti mimo je ti, ti Ola Re ga si ni alakoso Arisiki fun gbogbo eda Re, eleyi ti eniya naa je okan nibe. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا مِن دَآبَّةٍ فِي الأَرْضِ إِلاَّ عَلَى اللّهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ" {هود/6}

“Ko si eda kan ti o wa ni ori ile afi ki o je pe Olohun ni nse arisiki re, O mo ibugbe re ati aye ipamon re, Gbogbo re ti wa ninu akosile ti o han kedere”. (Suurah Huud: 6)

Botiwu ki eda ya ole to (Arisiki) Ije – imu ti a ti pin fun yio san wa ba a. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَكَأَيِّن مِن دَابَّةٍ لاَ تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ" {العنكبوت/60}

“Meloo meloo ninu eranko ti ko le da bukata ije – imu re gbe, ti Olohun si n se ije imu fun oun ati eyin, Oun (Olohun) ni Olugbo, Olumo” (Suurah al – Ankabuut: 60)

Sugbon Olohun maa n fun eni ti O ba sise lati wa Arisiki larisiki re. Olohun ti Ola Re ga ba Maryam (ki Alaafia Olohun maa ba) soro lasiko ti o nilo iranlowo pupo, ti o si je ole ti kole da ohunkankan se, bakannaa ti o tun n robi lati bimo:

"وَهُزِّي إِلَيْكِ بِجِذْعِ النَّخْلَةِ تُسَاقِطْ عَلَيْكِ رُطَبًا جَنِيًّا" {مريم/25}

“mi iti igi dabidun titi, dabidun tutu ti o ti to kaje yio jabo lati ori re” (Suurah Moryam: 25)

Olohun Olutoju wa, Oba ti Ola Re ga ko gbe Ije – Imu re dide fun – un, ki o waa so fun pe gba ounje ki o maa je, bikose pe, o pa lase ki o se ohun ti o maa je okunfa ohun ti o maa fa (Arisiki) ije – imu waa ba a ni. pelu pe ki o mi igi dabinu ti o wa legbe re si ona odo ara a re, ki dabinu tutu ti o to kaje si maa jabo sile fun – un.

Koda titi to fi dori awon eye ati awon eranko ti a kole gbo oro won ye, ati awon miiran ninu eda, kosi okan ti o maa n joko ni ile re ki ije imu fi waa ba a nibe bikose pe Olohun fi okunfa ije – imu re sibi ki O wa a, nipa bayi yio maa wa sise ni gbogbo igba lati maa wa ije – imu. Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) sope: “Ti e ba le maa ba Olohun duro ni papaa biba Olohun duro ni, won ko ba maa pese ije – imu fun yin gege bi won se maa n pese ije – imu fun eye, ti yio jade lowuro pelu ebi ti yio si pada sile ni irole leni ti ikun re o ti yo gbendu”.

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) wa salaye pe itumo wi pe yio jade lowuro pelu ebi ni pe yio lo lati wa ije – imu ni nkan ti ebi n pa, bakannaaa ti yio si seri pada si ile tabi itere ni nkan ti O yo gbendu, ti yio si ri ije – imu re nirorun.

Oro yi ki i se enu wi pe ki a kan gbara le Olohun nikan lai se ise, gege bi eni ti o ba ni ojulowo igbagbo ododo yi se maa gbara le Olohun lo tun gbodo tera mo ise sise pelu. Islam ko pepe lo sibi ki a joko lai sise, ki a pe ati gbara le Olohun, bikose pe o pepe si ki a wa ise se leyinnaa ki a wa gbara le Olohun. Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Ki enikookan yin maa mu okun re loo fi di igi idanan, ki o wa ru seyin re, ki o ta a, ki o wa jeki Olohun to oun pelu e, je ohun ti o lore fun ju ki o maa wa lo toro lowo awon eniyan, won fun – un tabi won o fun rara”. (Bukhariy lo gba a wa).

Kosi iyemeji pe gbogbo nkan ni o maa n ni okunfa leyin gbigbe ara Olohun, Tori pe ti ko ba je pe igbarale Olohun papo mo ise ti yio je sababi ni, Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) kiba ti so fun eniti o beere lowo re pe, se ki n tu Rakunmi mi sele, ki n wa ba Olohun druo? ojise Olohun dalohun pe: So Rankumi re mole, leyinnaa ki o wa sese gbarale Olohum.

Nipa bayi, maa se ise, ki o si maa wa ona lati le ri Oore ni ibamu si ohun ti Olohun ko mo o, ninu nnkan ti o tun towasonan nipa eleyi ti a wi yi, ni pe Arisiki ko se e fi agbara ri, tabi ka pe ko se e fi ogbon tabi ete kan ri. wa ri awon ti won ni Iwe eri nlanla lori eko giga ti won o tun maa pada sise labe awon ti ko to won ninu eko ati nibi mimo ise se daadaa, Nipa bayi, Owo Olohun ti Ola Re ga ni Arisiki eda wa, kosi lowo elomiran Kankan, Nipa bayi, mase paya fi okan bale lori Arisiki ti Olohun ko mo o, yio de odo re. Olohun ti Ola Re ga so pe

"قُل لَّوْ أَنتُمْ تَمْلِكُونَ خَزَآئِنَ رَحْمَةِ رَبِّي إِذًا لاَّمْسَكْتُمْ خَشْيَةَ الإِنفَاقِ وَكَانَ الإنسَانُ قَتُورًا" {الإسراء/100}

 “Ti o ba je pe eyin le ni ikapa lori awon apepe oro ike Oluwa mi, nigba naa nse ni e maa di i mowo ni ti iberu osi, Eniyan si je ahun”. (Suural al – isroo: 100)

2. IBERU NIPA ISORO: Gegebi isoro awon aisan sise, awon Adanwo ati bee bee lo, Gbogbo eniyan ni o maa n beru awon aisan, ti o si maa n paya fun awon isoro, Botiwu ki idaamu okan, ibanjuje, ati inira le po to, biberu won kose ayipada nKankan, bikose pe o tun salekun aburu, aisan, ati titankale isoro si ni. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِن يَمْسَسْكَ اللّهُ بِضُرٍّ فَلاَ كَاشِفَ لَهُ إِلاَّ هُوَ وَإِن يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلاَ رَآدَّ لِفَضْلِهِ يُصَيبُ بِهِ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ " (يونس: 107)

“Ti Olohun ba mu inira ba o, ko si eni ti o le mu un kuro ayafi oun nan, Ti O ba si gbero oore kan fun o, ko si eni ti o le da oore Re pada. O n se (oore) fun eni ti o ba fe ninu awon erusin Re. Oun ni Alaforijin Alaaanu” (Suurah Yuunus: 107)

Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “Enmo ni oro olugbagbo ododo, tori pe gbogbo oro re oore ni, ko si iru eleyi fun enikankan ayafi olugbagbo oododo nikan lo wa fun, Ti idunnu ba sele si yoo dupe, eleyi yio si di Oore fun – un, bakannaa ti inira kan ba sele si yio se suuru, eleyi yio tun di oore fun – un”. (Muslim lo gba a wa).

Awon alaye idanileko Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) fun awon Musulumi lori gbigba adanwo monra ati ona abayo lati dekun adanwo je alaye kan toye yekeyeke, Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so fun omo re Obinrin (oun naa ni Zainab, ki Olohun ba ni yonu si i) O ranse si Ojise Olohun lati pe ki won ba oun pee wa, bakannaa ki won ba oun so fun pe Omo Okunrin oun ti salaisi, Ojise Olohun si sofun eni ti won ran si pe: Pada si odo re, ki o so fun pe: tolohun ni ohunkohun ti o ba gba, ti E si tun ni ohunkohun ti o ba fun ni. gbogbo nnkan lo si ti ni igba ti a bu fun lodo Re, e ba mi so fun pe ko se suuru, ko si fi suuru re yi wa esan lodo Olohun. Okunrin ti o ran si Ojise Olohun yi si tun pada de, O so fun pe: Zainab bura pe oun fe ki Ojise Olohun gangan o wa, eni ti o gba Hadith wa so pe: Annabi (ti ike ati Ola n be fun) si dide, Sa’adu Omo Ubaadah naa dide pelu e, Muadh Omo Jabal naa dide pelu won, emi (eni ti o ran si Ojise Olohun) naa si tele won, Ojise Olohun si gbe Omodekunrin naa soke, lasiko ti emi omo naa n so pokanpokan bi igba ti omi gbigbona n so, nipa bayi omi ekun bere si ni jade lati oju Anabi mejeeji, tori idi eyi, Sa’adu beere lowo Ojise Olohun pe: “Kinni itumo ekun eyi ti iwo Ojise Olohun naa tun nsun? O dahun pe: Aaanu Olohun ni eleyi, o si je ohun ti Olohun maa n fi si okan awon erusin re. dajudjau Olohun maa n saanu awon erusin ti won je alaanu”. (Sohih Muslim)

Suuru je ohun ti won fe ki a se, sugbon leyin ti a ti se awon ohun ti o je (Sababi) Okunfa idinan isoro ni, eni ti ara a re ko ba ya, ko gbiyanju wa oogun lo si, Ojjisi Olohun (ti ike ati Ola n be fun) so pe: “E maa lo oogun si awon aisan to ba n se yin, tori pe Olohun ko so iwosan kan kale ayafi ki o je pe, o so iwosan re naa kale pelu, ayafi iku ati ogbo”. (Ibn Hibaan lo gba a wa).

Gbgobo aisan to wa laye yi patapata lo ni oogun, gegebi Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) se sa laye pelu gbolohun re yii: “Olohun ko so aisan kan kale ayafi ki O je pe o ti so oogun re naa kale pelu re, eni ti ko mo ni ko mo on, eni ti o si mo – on ni o mo – on”. (Ibn Hibaan lo gba a wa).

3. Iberu iku: ododo ni iku, o si je ohun ti yio sele lotito, gegebi o se dawa loju pe leyin oru osan ni yoo kan, bakannaa leyin osan oru ni o kan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"كُلُّ مَنْ عَلَيْهَا فَانٍ {26} وَيَبْقَى وَجْهُ رَبِّكَ ذُو الْجَلاَلِ وَالإِكْرَامِ" {الرحمن 26-27}

“Gbogbo eni ti o wa lori ile ni o maa tan. O si ma seku oju Oluwa re, Oni -titobi, Alaponle”. (Suurah a-r Rhamoon: 26-27)

Ko si ibi ti a le salo fun iku, ko si ibusasi kan ti o le gbawa lowo iku, tori pe, ti a ba sa, a o sa lo pade re. Olohun ti Ola Re ga so pe: So pe:

"قُلْ إِنَّ الْمَوْتَ الَّذِي تَفِرُّونَ مِنْهُ فَإِنَّهُ مُلاَقِيكُمْ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَى عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ" {الجمعة/8}

“Dajudaju iku ti e n sa fun, dajudaju yio pade yin. Leyin naa, won yoo da yin pada si odo Olumo – ikoko ati gbangba, nigba naa O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise” (Suurah al-Jum’ah: 8)

nkan ti o leto fun e lati maa ro nipa iku ni ohun ti yio sele leyin iku, ki i se nipa iku gan – an, gan – an, tori pe imaa ronu nipa iku gan an fun ra re yio gbe eniyan loo se ohun ti ko leyin, bakannaa o si je okan ninu awon nnkan ti o maa n ko susu bani lori ise ati lori amuse ero eni. O si maa n fa ibanuje ati idaamu okan eleyi si maa n le oriire jinaa. Nipa bayi, ohun ti yio sele dandan ni, ohun ti a si fi asiko ti a mo si ni. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلِكُلِّ أُمَّةٍ أَجَلٌ فَإِذَا جَاء أَجَلُهُمْ لاَ يَسْتَأْخِرُونَ سَاعَةً وَلاَ يَسْتَقْدِمُونَ" {الأعراف/34}

“Akoko ti wa fun ijo kookan, nigba ti akoko won ba si de, won ko le sun un siwaju di akoko miran, won ko si le fa a seyin” (Suurah Al – a’raf: 34)

Ninu awon nkan ti igbagbo nipa iku da lejo ni igbagbo nipa Igbende leyin iku, Igbagbo ninu Akojo Ojo Ikehin, Igbagbo ninu isiro ise, igbagbo ninu oriire tabi ori buruku, eni ti o ba ni igbagbo si eleyi, okan re yio bale, yio si le maa gbaradi pelu awon ise rere, yio di eni rere, yio si le se atunse awujo ti o ba wa naa daradara, Yio le se daada fun ara a re ati fun elomiran, ko si ni le maa banuje lori ohun ti o ti bo fun – un, tabi ohun ti o bo mo lowo ninu awon iwo re lonan abosi, tabi lona jije eto re mole, tori pe apadasi gbogbo nkan ni pe, yio tan, isiro ise naa si ni yio gbeyin re.

Leyin awon alaye yi, ti o ba bi mi leere wi pe: Nje O ti le se akolekan ofin esin Islam bi? Loju ese, lai ni fikan pekan, maa da e lohun pe: "Beeni", Nje O mo idi eyi? Tori pe mo ti ri idahun si gbogbo awon ibeere ti o maa n da opolo mii laamu, mi o si ri ohun ti o tako lakaye tabi ti o tako agbekale oro ti o ni alaafia, geegbi o se je pe mo tun ri ifeserinle ati ifokanbale, emi, eyi ti o se tan lati se amulo igbagbo ododo ninu Olohun, ati sise awon ise ipanilase Re, ati jijina si awon ise ikofunni Re, ati asopo todan moran lawujo, ati idaabobo awon eto elomiran, ati ipepe sibi awon iwa alaponle, awon iwa rere, ati jijinaa si awon iwa buruku, to fi dori awon iwa buruku keekeeke. Nipa bayi, pelu ofin yi, Islami ti so mi, o si ti so elomiran yato si mi. gbogbo eleyi ni o n je amuse oriire fun mi, oriire eyi ti gbogbo eniyan n le ni agbaye, ti won si n fe amuse re, ti won si n na gbogbo ohun ti won ni lagbara lati le ri i. mo wa n bi iwo naa leere pe, nje o tile ti ri awon erogba re ti o ni lokan siwaju bi? Ti o ba je pe O ko ti i ri ohun ti o nfe, a je wi pe adisokan lati maa se ibaje ni adisokan re. ti o ba si je pe die lori ninu amuse adisokan re, a je wipe adisokan aladinku ti ko pe ni adisokan re. lopin igba ti o ba si je pe adisokan je aladinku, a je wipe o ni lati wa omiran ti o pe, ti a o fi paaro eyi ti kope yi. A je wi pe, gbogbo enikookan wa ni ki a maa wa eyi ti o lola julo fun wa.

 

 

NJE O MO ESIN TO PE PEREPERE?

Islam ni esin to pe perepere, esin yi si ju owo re mejeeji sile fuu o, O nso fun e pe: maa bo wa si odo mi, gbogbo ohunkan to wu o lo maa ri lodo mi.

O see se ki o mo lero tabi ki o ti mo so pe: boya mo je eni ti o n se eyameya, ti o n pepe si esin re lati se eyameya, eto re ni lati so ohun ti o ba wu e! sugbon, ti mo ba maa so fun e pe emi nikan ko lo so iru oro ti mo so yi o, bikose pe awon elomiran ti won ni arojinle ti won si je olopo ironu, onideede, tiwon ki i se Musulumi, awon naa so iru ohun ti mon n so yi, awon to je pe won maa n ronu si oro daadaa lati wo boya ohun ti o le sele ni tabi bee ko, Bakannaa ti won ma ndajo pelu deede. Ara iru awon eniyan bee ni (J.S Restler) nigba ti o so bayi nibi oro Itisiwaju Iwe re ti o pe ni “Olaju awon Larubawa”: “Oruko ti Islam n je, o see se ki o je pe won fayo wa lati ibi itumo meta otooto: Ituumo Alakooko ni esin, itumo keji ijoba sise, itumo Elekeeta: Olaju. Nisoki: Imo olaju ti ko ni afiwe”

Bee si tun ni eniti o mu esin Islam ni ota gan – an tun so pe esin ododo ti o pe ni Islam, Won a maa pa lowe bayi pe: “Ohun ti awon ota ba serisi pe ododo ni, ohun ni Ododo”

Margoliouth eni ti won mo pe o maa n tako Islam, ti o si je ota Islam, sugbon titobi Al – Qur’an ko di lowo titi ti o fi le so ododo, O so pe: “Ohun ti gbogbo awon oluse iwadi nipa Al – Qur’an ni won panupo pe al quran ni ipo nla larin awon tira yoku, ti osi jepe oun ni o gbeyin de ninu won, o wa gbawaju gbogbo won latara ilapa re ti o ko idamu ba awon eniyan, o ko awon irori tuntun sinu, ati awon ipile iwa ti o dara”.

Kin wa ni o fa ti o fi wa n tako Islam, tabi ki a wule so oju abe niko, kin lo fa ti o fi gba Islam, Se nitori pe Islam n pe ni lo sibi imolohunlokan ni? abi se nitori pe o n pepe sibi ki eniyan maa sin Olohun, yato si eda abara? Abi se nitori pe o npepe si iwa Alaponle ni? abi nitori pe o n pepe sibi deede sise, ati jijinna si abosi sise.

Abi nitori pe o se awon eniyan ni dogbandogba lodo Olohun? Abi nitori pe O ko gbogbbo eto ti o wa fun omoniyan sinu, la i wo awon adisokan ti won ni, eya ti won je ati awo won? Ati bee bee lo.

Oro kan n be ti o le ni ilapa nibi ayipada adisokan re. Laarin asiko (ogorun merinla odun seyin) esin islamu nlekun lati igba ti o ti han di asiko yi, gbogbo Eni ti o ba ka nipa islam pelu arojinle, ti ko si gbe ife – inu wo o, ti ko si se eyameya esin, yoo gba lati pe ododo ni Islam, koda bi ko tile wo inu Islam naa, sugbon won o ba islam se ota, bi awon ifunpinpin se po to fun awon ti ntele esin islam, yala nipa abala sisowona, abala oselu, abala awon Agbe – ofin – ro.

Woye si asiko wa yi,, won gba islam mu ati awon ofin re, ti o ba fe apejuwe die, gba lapejuwe ifowosowopo (sufeti) ti won ti lo, won deru ba awon musulumi larin adorin odun, won wo awon mosalasi won, won yi awon oruko won pada, won ko fun won lati fi esin won han, leyin igba ti awon ijo yi lo tan, awon ilu musulumi imiran tun han ninu won, eleyi ntoka wipe bi gbongbo islam kan ba ku ni ita, yio fi idi mu le ni inu.

kinni eleyi n toka si? Se ki i se pe ohun toka wipe esin to ni alaafia ni esin islam eyi ti awon eniyan o ti maa ri oriire won, ti okan won naa yio si fi le maa papo? Eni ti opolo re pe, ti n se iwadi ododo ati ojulowo iwadi nigbakigba ti won ba ti n ka akosile nipa Islam, laelae won ko le ri nnkankan ninu awon eko Islam ayafi ki o je pe a o ri gbogbo nkan ti o n pepe si ni iwa alaponle, iwa rere ni yio je, ati pe ki won O tun ripe O n ko idakeji awon wonyi. Awon opolopo ninu awon ti kee se Musulumi awon ti o je pe won ko ri ohun ti O le wo won san nibi kudie kudie won nibi awon esin ti won gba, bakannaa ti ko si ohun to le fa o rii re ba won, Won ti dan gbogbo nnkan wo, ayafiIslam nikan, Ti won ba ye Islam wo ni won ko ba ri gbogbo ohun ti won n wa nibe, ati gbogbo ohun ti o le so oriire di amuse fun won, Iwadi ti ko nii mu asise dani ni, ninu ki o je pe yio fa eniyan lo sinu ike ati oriire gbere tabi ki o je ohun ti a o maa fi Olohun wa iso nipa ori buruku ati nipa iya gbere. Beere lowo ara re pe kinlode ti o fi je pe Islam nikan ni won maa n gbogun ti? Kinlode to fi je pe Ilsam nikan lo n da ija ja lori ki koju awon esin yoku? O pe ti won ti maa n so pe: “Ota ni omoniyan maa n mu ohunkan ti ko ba mo. Nipa bayi ma je alaimokan, bikose pe ki o ko imo, ki iwo naa o si ko eleomiran, ki awon alaimokan ma fi le seku mo laarin wa". Ibere ni eleeyi, jeki emi re ro lati gba ododo, ki o si tete si abala keji naa, ki o si je ki iteti si ododo re le je ki o da ododo mo. Ki o si maa be Olohun lopolopo lati pe ki o maa fi ona mo o losi oju ona ti o ni alaafia, eleyi ti yio mu o de ibi esin dodo, eyi ti yo so ojulowo oriire di amuse fun o. Nighati Olohun ba ti mo o mo ododo, nitoripe o da ododo mo, o si n tele, laelae koni yepere re mo.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِينَ كَذَّبُوا بِالْكِتَابِ وَبِمَا أَرْسَلْنَا بِهِ رُسُلَنَا فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ" {غافر/70}

“Awon ti won pe Tira naa ati ohun ti A fi ran awon Ojise Wa niro, laipe won o mo". (Suurah Goofir:70)

Kinlofa ti opolopo awon Alfa, ati awon Eleko, ati awon ti won maa n ro arojinle ni abala iwo – oorun aye ti won je awon ti ki i se Musulumi, nigba ti won ka nipa Islam won si gba Islam, won si se Islam naa daada?

Mo bi o pe, kinlofa? Nitori pe won mo titobi Islam leyin ti won ko Islam fun rara won. Sugbon won ko mo awon Idajo won yii lori awon idajo esin to ti gbawaju ti o wa fun awon miiran. Won ri awon nkan ti won wa, ati oriire ti temi. Awon eniyan bee ni bi: Lyoeblad fays, Itandiniya, Lurad habdaley, Rehnojegeow, Doctor Jeryneayyha ati awon opo eniyan miiran.

nbe Ninu awon Alarojinle wonyi eni ti O ka nipa Islam sugbon ti o tun seku sinu esin re, ti awon oro ododo, ati rinrinle ewa Islam ati pipe ti Islam pe, are ninu won ni Doctor Lawaral Faysha Faleary ati Doctor Zagrad Hoeniquy, ati ojogbon kan ti o nje Juutar Lemanon, Tumas Karlay ati bodylae toilaystiwea, ati laamartain ti o je akorin ni(persial) pasia ati Barnatidshow eni ti o so pe: Dajudaju o je dandan ki Muhammad pepe fun yiyo omoniyan lofin, emi lero pe ti iru okunrin bii re ba sakoso aye ode – oni, ki ba yege nitoripe yoo wa ona abayo sawon isoro pelu ona ti o le fa alaafia ati oriire ba aye. Awon topo miiran naa tun so bee sugbon pelu febe Olohun ati ogo Olohun ni eda fi n ri imonan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّكَ لاَ تَهْدِي مَنْ أَحْبَبْتَ وَلَكِنَّ اللَّهَ يَهْدِي مَن يَشَاء وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ" {القصص/56}

“Dajudaju iwo ko le fi ona mo eni ti o feran, sugbon Olohun ni n fi ona mo eni ti O ba fe” (Suurah al – Qosos: 56)

Kii se pe aaya yi je awijare, ki won fi maa so pe kadara ti gbawaju lori eniyan bikose pe ki won ripe won sise. Aliyu Omo Abu Toolib (Ki Olohun ba ni yonu si) sope: “A n be nibi Janazah kan ni aye ite kan ti won n pe ni Baqiihil Garqod. Ojise Olohun (ti ike ati Ola n be fun) wa ba wa, o ba joko, awa naa ba joko, legbe re, o mu opa ti o se fara ti dani, o si fi opa naa te ile, o ba fi opa yi gbe iho kan lori ile, leyinnaa o so pe: “Ko si eni kan ninu yin, ko si si emi ti n mi ayafi ki o je pe Olohun ti ko aye re lalujannah ati ina sile telete, bakannaa ki Olohun si ti ko akosile boya oriburuku ni yoo se tabi oriire. Aliyu Omo Abu Toolib (ki Olohun bani yonu si) so pe, okunrin kan ba so pe: Iwo Ojise Olohun: se ki a kuku fe e kan maa joko nile ki a gbarale akosile wa, ki a pa ise sise ti? O dahun pe: Eni ti o ba je ara awon oloriire, yoo maa se ise ti awon oloiire maa n se ni, bakannaa eni ti o ba je okan lara awon olori – buruku, oun naa yoo di eni ti yoo maa se ise awon olori – buruku. leyin naa ni o ka Ayat yi.”

{فَأَمَّا مَنْ أَعْطَى وَاتَّقَى، وَصَدَّقَ بِالْحُسْنَى، فَسَنُيَسِّرُهُ لِلْيُسْرَى، وَأَمَّا مَنْ بَخِلَ وَاسْتَغْنَى، وَكَذَّبَ بِالْحُسْنَى فَسَنُيَسِّرُهُ لِلْعُسْرَى} [الليل: 6]

“sugbon eni ti o ta ore ti o si beru (Olohun), A o se daada ni irorun fun, sugbon eni ba se ahun ti o si roro, ti o si pe (aljannah) ni iro, A o se aburu ni irorun fun” (Muslim lo gba a wa).

Opolopo awon ara ila – oorun aye ti o ko eko nipa Islam pelu afojusun a ti le gbogun ti Islam ni won pada di eni ti o gba Islam latari ewa Islam, nitori eto Islam, bi ba opolo mu ofin Islam, agbekale oro Islam ati adamo Islam. D. Potter so pe: “Islam ni esin ti o je ofin Olohun, a ri i ni nti alaye re ye yekeyeke nibi adamo re, pelu ase Olohun nikan soso si ni awon oke nlanla fi n rin, ati awon ibudo nlanla, awon irawo naa maa n rin lojuona ti won naa pelu ase Olohun nikansoso. awon irawo yii naa si n teriba fun ase Olohun, gegebi awon eniyan naa se maa n teriba fun awon olori won, Olohun lo ni apejuwe ti o ga julo, bee si ni awon nnkan wonyi ko le soro, won kosi le se nnkankan ayafi ohun ti Olohun ti ko sile fun won, gbgbo won si da bi horo irugbin legbe ohun ti o wa ni aye yi ni – koda to fi dori awon nnkan oborogidi won gbafa fun Olohun sugbon omoniyan nikan lo yo kuro nibi ilana yi, tori pe Olohun fun omoniyan lanfaani ki o yan eyi ti o ba wu. Idi niye ti o fi je pe O le gbafa fun ase Olohun toba wu, O si le fi awon ofin ti e lele, ki o si maa samulo re fi se esin to ba tee lorun, o je ibanuje okan wi pe o maa n yan oju ona keji lopolopo igba (Ojuona keji yi ni ona ife inu re)…. Opolopo eniyan ni ilu awon alawo funfun (Europe, America) ni won n gba Islam nitori pe won ti ri isinmi emi ati ifokanbale emi (ninu Islam), Koda opolopo awon ara ila oorun aye ninu awon ti won je elesin kirisiti ti won gbe ipinnu lati wo ofin Islam, won pada di Musulumi. Eyi ko sa dede ri bee, bi ko se pe ododo maa n ni eri ti kii ni atako”.

Gbogbo esin yoku yato si Islam – gege bi esin Kristi (Omo leyin Jesu), esin awon (yaudi) lo pe laye johun ko too di pe won yi awon nnkankan pada, opolopo nkan ti laakaye to pe kole gba wole ni o wa nibe, bakannaa ti o si tako adanmo ti o ni alaafia, eleyi ti eniyan ti o dape gbodo ko, kin ni o fe so nipa awon ( Asiwaju esin to yato si Islam yi).

At – taorah ni tira kan, ti Ojise re si je Musa (ki Ola Olohun maa be fun – un) tira yi si ni o mu esin ti o gbawaju wa, leyinna ni o kan esin Nasaaroh (esin Kristi) Ojise ti e ni Hisa (ki ike ati Ola maa ba) eniti o wa pari esin Musa (ki ike ati Ola Olohun maa ba) ti Anabi Muhammad (ki Ike ati Ola Olohun maa ba) si je eni ti o w ape esin anobi Hisa, o je ikeyin awon Anabi Olohun ati awon Ojise Olohun (ki Ike Olohun ati Ola Re maa ba gbogbo won) pelu idi eyi ni Islam fi je eso gbogbo esin patapata eleyi ti o je dandan fun gbogbo eniyan lati gba a.

 

 

IRUJU NIPA ISLAM

Ma so fun mi pe “Kani Islam dara ni awon Musulumi ki ba dimu lesin funrara won daada”. Oro eleyi koje nnkankan bi ko se abajade irori buburu ti omoniyan maa n ro nigbati won ba woye so eniyan meji tabi meta tabi egberun, Sugbon, se o boju wo ogoro awon Musulumi ti onka won po koja (milyar) kan ati aabo ni agbaye, O se idajo Islam latari idajo kan ti o wa lati owo awon eniyan die.

Islam je esin ti o ni eto, gbogbo eto lo si ni awon ti o tele, nitoripe won mo abajade to dara ti o ni. Bakannaa ni awon ti won o yapa si, awon nan won o ri esi iyapa won.

Eto ilu ti won gbekale fun irinnna ati fun idaabo bo emi, ti enikan tabi eniyan meji tabi meta ba koja ala re, se a o se idajo wi pe gbogbo awon ara ilu ni won yapa eto ni? abi won o so pe ofin ni kodara? Gege bi O se je pe eni ti o yapa eto naa tun le moribo nibi ijiya nigba akoko, ekeji ati eketa, sugbon ojo kan yio waye ti abajade iyapa ofin lori ohun ti o se, ti isele kan yio se okunfa iku re, tabi ki isele yi fa adanwo wa fun, aburu ti o se pe o le moribo kuro nibe to ba je pe O tele eto! Bayi gele ni Islam ri, tori pe awon Musulumi kan n be ti won n lo awon eko Islam daadaa, bakannaa awon Musulumi miran si wa ti won ki i lo eko Islam daada, Eleyi ti o je pe,, kani won ti e moribo nibi ijiya aye lori ailo eko Islam dada, won ko le moribo nibi iya ti torun, Eleyi sin be fun gbogbo esin pata, ki i se Islam nikan.

Esin juu (Yehudi) fun apeere, Nje gbogbo awon to n se esin Yehudi yi lo n lo awon eko ti esin won ko won, abi a ti e le ri awon ti ki i lo awon eko naa daadaa, Ninu esin Nasaroh bakannaa, se gbogbo awon to n se esin yi lo n lo awon eko esin won, abi a ti e le ri awon ti ki i lo gbogbo eko esin naa? “Gbogbo agbekale oro lo ni ayokuro”, geege bi won se maa n so.

Mo mo pe ati ni ipinnu (lori nkan ti a n soro re yi) o soro, sugbon okan akin ni o bukata si, mo n be Olohun ti o tobi ki o bani di owo re mu, ki o si fi ona mo okan re, ki o si to e sona ododo, ki o si si okan re sile fun ododo. Mo n gbero ojulowo oriire fun o, ki Olohun je ki o ri bee. (Amin).

 

WWW.ISLAMLAND.COM

[email protected]