AWON IRUJU NIPA AWON ETO OMO-ENIA NINU ISLAMU

AWON IRUJU NIPA AWON ETO OMO-ENIA NINU ISLAMU

AWON IRUJU NIPA AWON ETO OMO-ENIA NINU ISLAMU
شبهات حول حقوق الإنسان في الإسلام باللغة اليوروبا

 

Dr. Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة


Itumo ni ede Yoruba
European Islamic Research Center (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Abd Ar-Razzaq Isa
Atunto
Ridwan Allah Murtadho
 

www.islamland.com

 

NI ORUKO OLOHUN, OBA AJOKE AYE, ASAKE ORUN
ORO ITISIWAJU
Gbogbo ope ati eyin fun Olohun, ike ati ige ki o mo ba Anabi wa Muhammad, ati gbogbo awon ara-ile re, ati awon saabe re, leyinnaa:
Dajudaju gbogbo awujo ninu awon awujo omoniyan ni oje dandan pe ki o mo bee fun omoniyan kookan ti o wa nibe awon eto eyiti yoo mo mu won se awon ise ati awon ojuse won, ti won yoo mo gbadun pelu ifokanbale ati idurosinsin, ti yoo si se ifirinle ibatan won si awujo. Lara oun ti n be ni awujo agbaye ni asiko yi ni orisi ilana meta: Alakokoo; ni ilana ti o se aponle ati igbe ola fun omoniyan kookan lori awujo ti o si se leewo fun awujo lati dasi ominira re, o si fun ni awon eto kan eyiti koni onde ti o wa je okunfa fun ifaseyin isemi awujo ati fun awon iwa ibaje, eleyi ni ilana ti won npe ni "capitalism".
Ilana keji ni eyiti o se aponle ti o si gbe ola fun awujo lori omoniyan kookan, ti o si gba lowo omoniyan kookan erongba ati eto re. Omoniyan ninu awujo yi je alaini erongba, ti kosi ni eto kankan ju oun ti awujo ba fun un lo, eto ti yoo je oun isin fun anfaani awujo, ilana yii ni eyiti won npe ni (communism). Ilana keta ni eyi tosepe ko gbe ola fun eniyan kookan lori awujo tabi awujo lori omoniyan, sugbon o fun enikookan ni eto re. Omoniyan kookan ni eto re lori awujo gegebi awujo naa se ni lori omoniyan awon eto toni onde, ofin ati majemu. Ilana yii je eyi ti o gbe-ola fun anfaani awujo lori anfaani adani nigbati won ba figagbaga.
A o se alaye tokun keke laarin awon oju ewe wonyi nipa awon eto omoniyan labe ofin esin Islam lati inu Tira Olohun ati Sunna ojise Re Muhammad-ki ike ati ola Olohun maa ba- eyi ti o je ipile meji akoko fun Islam. Awon eto wonyi je eyi ti won nfe lodo omoniyan, ki o le je omoniyan rere nibi iroyin re ati nibi ibalopo re pelu elomiran. Mo ni amodaju pe oore omoniyan ati sisele ohun ti awon awujo nrankan re nibi ifokanbale, ilosiwaju ati idagbasoke nbe nibi lilo awon eto wonyi ati fifi se ise, toripe awon eto yi kiise nkan tuntun tabi irori awujo tabi bukata asiko tabi ilana iselu. Ohun ti o mumi ni amodaju lori oro mi nipe eniti ofi awon eto yii lele ni Oluseda omoniyan Onimimo nipa alamori re ati ohun ti yoo je anfani fun isemi re. Nipaapa ipile ofin Islam (Al-Qur'ani alaponle ati Sunnah tomo kanga) eyi ti o kun keke fun awon eto wonyi ti won si se ifirinle won, ti o si je pe ohun akoko ti o fi lele ni isaponle omoniyan lori awon eda miran, Olohun so bayi pe:
" وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلًا (70) "
" Atipe dajudaju Awa se aponle fun awon omo (Annabi) Adama,
Awa ngbe won rin lori ile ati odo, Awa si nfun won ni ije-imu ninu awon ohun ti o dara, Awa si da won lola ju opolopo ninu awon eda ti A da niti ola." Suratu-l-Isra':70.
Ise aponle yii je oun ti nbere fun awon eto kan eyiti yoo se afirinle ilosiwaju re, ti yoo si tun se afinrinle ominira re lati lee maa gbe ile-aye ati lati leese igbedide jije arole lori ile eyiti Olohun ti ola Re ga nsalaye pelu oro Re bayi:
وَهُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلَائِفَ الْأَرْضِ وَرَفَعَ بَعْضَكُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ "
"Oun na ni eniti O se yin ni arole lori ile, O si gbe apakan yin ga niyi ju apakan lo …" Suratu-l- An'am 6:165.
Awon eto omoniyan ninu Islam kii se eto fun un ni ile-aye nikan, bi kii sepe awon eto wonyii tun tesiwaju laisi idaduro koda leyin iku. Ninu eto re ninu Islam nipe ti o baku ki won we e, ki won fi lofinda dundun si lara, ki won wo o laso funfun tuntun, ki won osi kirun si lara, ki won si se adua fun un. Won gba wa lati odo Abi – Hurayrah to sope: mo gbo Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun maa ba- ti nsope: ti eba kirun si oku lara, eya se afomo adua yin fun un " Abu Dawuud ati Ibn Hibban logba wa." Gbolohun pe (eya se afomo adua yin fun un) tumo si pe e se adua fun pelu ise afomo re fun un pelu ini afiyesi adua ti e nse".
Sharia Islam si se leewo iyepere re abi sise ibaje pelu re gegebi gige apakan eya ara re nitori oro Onse Olohun-ki ike ati ola Olohun maa ba- to sope: ki kan eegun oku da geggebi kikan an nigba ti owa laye." Abu Dawuud logba wa.
Bakanna ni won se leewo wiwu saare re, abi jijoko le e lori, abi ririn lori re, nitori oro onse Olohun-ki ike ati ola Olohun ma aba- to sope: ki enikan ninu yin joko lori oguna ki o wa jo aso re ki o wa jo ara re, o loore fun un ju ki ojoko lori saare lo o." Sahihu Muslim.
Gegebi o se jepe ninu eto re ni sise idaabobo fun omoluabi re ati jijina si ima so oro aburu nipa re koda leyin iku re. Won ti gba wa pe Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun maa ba- so bayi pe: ema so nipa daada awon oku yin, ki esi jina si siso nipa aburu won." Abu Dawuud, Tirmidhi, Hakim ati Bayhaqi logba wa sugbon o le.
Bakanna ninu eto re lori awon omo ati alasunmo re ni ima wa aforijin ati ike fun un ati ima mu asotele ati adehun re se leyin re, nitori oro onse Olohun-ki ike ati ige Olohun ma aba- fun arakunrin ti obere lowo re pe: Ire onse Olohun: nje nkankan tun seku fun mi nibi sise daada si awon obi mi leyin iku won? Ojise Olohun sope: be ni i, ima se adua fun won ati wiwa aforijin fun won, ati ima mu ileri won se leyin won, ati ima so okun ebi eyiti kole so ayafi pelu won, ati ima se aponle awon alabarin won." Abu Dawuud, Ibn Hiban, Ibn Majjah, ati Hakim logba wa, Al-Baani si sope Hadith to le ni.
Oseese ki oluka awon eto wonyi ri oun ti o joo ninu oun ti apakan awon ajo ati ile-ise kan npepe si gegebi awon ajo to nrisi eto omoniyan ati awon ajo to jo, sugbon awon eto ti Islamu mu wa saaju awon ajo ati ile-ise wonyi ni ntole ni ogorun merinla odun seyin. Ki asi tun lomo wipe awon eto wonyi ti awon ajo wonyi nse ifirinle re ni opolopo aleebu ati adinku ninu, toripe ni opolopo igba ni won ko fi won lele lati so eto omoniyan gegebi omoniyan.
 Sugbon ni opolopo igba won se afi lele won lati je iso fun eto omoniyan nitori anfaani ti won yoo ri lara re ati nitori lilo oye ati agbara re fun awon asunta kan, abi fun awon anfaani kan yala anfaani adani ni i tabi anfaani ileto. Eri lori oun ti aso yii nipe ati ri lopolopo awon eto ti won gba pelu agbara lodo opolopo omoniyan ni opolopo awon ileto, pelu eleyi a ri opolopo orile ede ti npepe ija fun eto omoniyan ti won po ti won si nse iranlowo fun abosi lati ra eto awon omoniyan lare. ki i sepe won ni agbara lati se ayipada re, sugbon nitori anfaani to wa fun won nibi mima dasii lati se ayipada oun ti won npepe re labe iboji ati lati le dasi awon alamori to niise pelu inu-ilu.
Paapa awon eto omoniyan ninu Islam koni etan ati imusere ninu. Umar omo Khatob-ki Olohun yonu si- nigbati gbigba Islam "Jablah" oba Nasaro larubawa de eti igbo re odunu si gbigba Islam re, leyinna o pee fun sise abewo Madina, awon kan sope Jablah ni o gba iyonda lati se abewo re osi yonda fun un lati wa. Nigbati ode Madinah owole to Umar osi ki, Umar naa si ki kaabo osi sunmo, osi se Haj odun naa pelu Umar. Laarin igba ti nse iyika Kaaba ni arakunrin kan lati idile Faz'ara ba te aso iro re mole, ni aso iro re ba kaa soke, bayi ni Jablah ba kan imu arakunrin naa, awon kan sope orun imu re po, ni arakunrin Faz'ari yii pelu opolopo awon ara-ile re balo si odo Umar lati gba eto re, ni Umar ba pe si ijoko re, Jablah sise ifirinle oun ti o se, Umar wa sope oun yoo gba eto re fun un, ni oba sope bawo ni yoo se gba eto re fun un nigba ti o je pe oba ni oun, ti arakunrin yi si je eniyan lasan ti ko ni ipo Kankan.
 Umar wa sope: Islam ti se idapo larin ire ati oun iwo ko ni ola lori re ayafi pelu iberu Olohun. Jablah ba sope: mo lero pe ma a ni aponle ninu Islam ju bi mo ti ni lo ninu Igba aimokan, ni Umar ba sope: pa iyen ti, ti o ko ba wa iyonu arakunrin yii emi yio gba eto re fun  un. Ni jablah ba sope: emi yio si pada si esin kiristani, Umar da lohun pe ti oba seri pada si kiristani emi yio ge orun re. Nigba ti ori idurosinsin yii o sope emi yoo woye si alamori mi emi yoo si seri pada si odo Umar. Nigbati odi ale oun ati awon ijo re gun nkan gun won, won si seri pada si ile Sham, o si wo ile roomu ti osi wole to oba Arkol ni ilu Kistantinia " Constantinople" Arkol si ki kaabo, osi fun ni Ilu nla ati oun ije topo, o si tun fun ni ebu torewa, o si se nikan ninu awon ijoye ati alasunmo re.
Nipaapa Islam tun tataporo nibi sise amojuto eto adani fun omoniyan debi ise amojuto awon eto elomiran ati iti abosi nu fun eniti won se abosi re, Olohun so bai pe:
"وَمَا لَكُمْ لَا تُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ وَالْوِلْدَانِ الَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْ هَذِهِ الْقَرْيَةِ الظَّالِمِ أَهْلُهَا وَاجْعَلْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ وَلِيًّا وَاجْعَلْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ نَصِيرًا"
Itumo:" Ehase yin ti enyin ki yoo fi ja si oju ona ti Olohun ati fun awon alailagbara ninu awon okunrin ati awon obinrin ati awon omode; awon tin wipe: Oluwa wa; Mu wa jade ninu ilu yi ti awon ara inu re je alabosi, ki o si fun wa ni oludabobo kan lati odo Re, Ki o si fun wa ni oluranlowo kan lati odo Re." Suratu-n-Nasai:75.
Awon eto yi je eyiti won se idabobo fun, fun awon musulumi ati eniti ki se musulumi. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma aba- sope: eteti ki egbo, enikeni ti o ba se abosi eniti agba adeun pelu re, tabi ofi abuku kan, tabi o la boo lorun oun ti oju agbara re lo, abi ogba nkankan lowo re laiyonusi, emi ni ma a je alatako re ni ojo igbende." Abu Dawuud ati Bayhaqi logba wa, Al-Banni si sope: Hadith toda ni i.
Ojise Olohun tun nsope: eteti ki egbo, enikeni ti o ba se abosi eniti agba adeun pelu re, tabi ofi abuku kan, tabi olabolorun oun ti oju agbara re lo, abi ogba nkankan lowo re laiyonusi, emi ni ma a je alatako re ni ojo igbende, leyinnaa ojise Olohun naa owo re si igba-aya re loba sope: eteti ki egbo, enikeni ti o ba pa eniti ase igbadeun pelu re ti oni iso Olohun ati ojise Re, Olohun se oorun alijannah leewo fun, dajudaju orun re je oun ti won ngbo lati irin ogorin odun."
Dajudaju lilo awon eto omoniyan eyiti Islam pase re ni awon ilu-Islam je oun ti o sopo mo iwon ba lilo ofin esin ati idajo re ni sisopo ti o lagbara. Owa ninu won eni ti o gbe gbogbo isemi re fun Islam, o si tun wa ninu won eniti nmu ninu Islam oun ti ose deede pelu awon anfani re, o si wa ninu won eniti npego si abe Islam lati le gbee subu ati lati fi abuku kan, nitori eleyi, eniti oba je enia oni lakaye olu se deede olu ronu jinle, paapa julo eniti kii se musulumi nigbati oba fe se idajo kan nipa Islam lori eto omo-enia o pondandan ki o woye si lori pe Islam je eto ati ofin ti o da duro, ko sopo mo isesi ati ise eniyan Kankan,tabi ijo Kankan, abi orilede Kankan, nitoripe lilo awon eto yi ni awon orilede Islam gegebi ase so siwaju je oun toni se pelu iwonba idunnimo lilo sharia ni awon ilu yi. Ti eto ba dara ti adinku si sele si aho won abala lilo re, toripe adinku ati alebu nigbakugba ma nsele nibi lilo.
Fun apejuwe; ti aba ri enikan ti n pepe Islam mo ara re ti o wa gbaroyin pelu awon iroyin ti okan ko gegebi iro pipa, ijanba, ailooto, nje eleyi tunmo si pe Islam npepe losi ibi awon iroyin yi bi? Oun to dara julo ni asiko yi niki won pada si ipile eko esin Islam ti oni Alafia lati mo paapa Islam. Bakaana ki won loo mo pe pipe ti Olohun nikan ni, adinku ki se oun adayanri fun awon musulumi nikan gbogbo omoniyan ni ole se asise ti abujenjeku si le sele lati odo won, yala ni isemi aye won ni, abi ni abala esin, abi ni abala ibasepo awujo.
Dr. Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
[email protected]
Islam ati Ise-Ojukokoro Lati Pase Oun Ti O Pandandan
Dajudaju ati nipaapaa Islam nse gbogbo ojukokoro lati gbe awujo ti o dara dide labe pipese ati ise afirinle awon oun to je oun ipile asemoni eyeti yio ma so fun omoniyan kookan ni awujo yi igbadun pelu awon eto won lati le je ki won ma gbadun pelu isinmi ati ifokanbale, ti won yio si ma semi nibe pelu ominira ti o jina si imunisin, ati lati le je ki won ma gbadun pelu isemi-aye adamo nibi awon eto won ti ofin Sharia yonda fun won. Ojise Olohun- ki ike ati ige Olohun ma a ba- so bayi pe: "eteti ki egbo, dajudaju awon eje yin, awon owo yin, awon omoluabi yin je eewo larin yin gegebi owo ojo oni yin ninu osu yin yi, ninu ilu yin yii" Esin Islam ngbiyanju lati se akojo awujo eyeti yoo wa ninu re:
1. Ifayabale pelu gbogbo aworan re nibi:
Ifayabale lori owo, Olohun so bayi pe:
" أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَأْكُلُوا أَمْوَالَكُمْ بَيْنَكُمْ بِالْبَاطِلِ إِلَّا أَنْ تَكُونَ تِجَارَةً عَنْ تَرَاضٍ مِنْكُمْ "
Mo pe enyin ti e gbagbo; e mase je oun-ini nyin laarin ara yin pelu ibaje afi ki o je owo-sise pelu iyonu yin,.." Suratu-n-Nasai: 29.
* Ifayabale lori omoluwabi eni: Olohun so bayi pe:
" وَالَّذِينَ يَرْمُونَ الْمُحْصَنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَأْتُوا بِأَرْبَعَةِ شُهَدَاءَ فَاجْلِدُوهُمْ ثَمَانِينَ جَلْدَةً وَلَا تَقْبَلُوا لَهُمْ شَهَادَةً أَبَدًا وَأُولَئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ"
Itumo: Awon ti won pe pansaga mo awon obinrin ti won kii se pansaga, lehina ti won ko ri eleri merin mu wa, e na won ni ogorin egba, e ko si gbodo gba eri won lailai, awon eleyi ni poki." Suratu-n-Nuur: 4.
* Ifayabale lori emi: Olohun so bayi pe:
" قُلْ تَعَالَوْا أَتْلُ مَا حَرَّمَ رَبُّكُمْ عَلَيْكُمْ أَلَّا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا وَلَا تَقْتُلُوا أَوْلَادَكُمْ مِنْ إِمْلَاقٍ نَحْنُ نَرْزُقُكُمْ وَإِيَّاهُمْ وَلَا تَقْرَبُوا الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَلَا تَقْتُلُوا النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللَّهُ إِلَّا بِالْحَقِّ ذَلِكُمْ وَصَّاكُمْ بِهِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ "
Itumo: " Wipe: E wa ki emi ka ohun ti Oluwa yin se ni eewo fun nyin; ki e mase wa orogun kankan pelu Re, ki e si maa se daradara si awon obi yin mejeji, ki e si ma se pa awon omo yin nitori iberu osi, Awa ni A npese fun yin ati awon naa, e si ma se sunmo awon iwa ibaje ni eyiti o han sita ninu re ati eyiti o pamo, ki e si mase pa emi ti Olohun se ni eewo ayafi pelu ododo, eyi ni O npa lase fun nyin ki e le ba se lakaye." Suratu-l-An'am 151.
* Ifayabale lori lakaye: Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun maa ba- so bayi pe: gbogbo oun ti ba nmuni hunrira oti ni, gbogbo oti si je ewo". Muslim logba wa.
Ko leto lati ma se ideru ba omoniyan, tabi idaya ja won, tabi imo tan oun iberu ka ni aarin won, yala pelu oro lile ni, toripe ni paapa won ti gbawa lati odo ojise Olohnu-ki ike ati ola Olohun ma a ba- to so bayi pe: enikeni ti o ba se idaya ja musulumi kan, o ti je dandan fun Olohun ki o ma se ifokanbale fun nibi iberu ojo igbende alukiyama." At-Tabaraani ni ogba wa, Al-baani sope o le.
Tabi pelu imo na owo nkan ija si won, ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: "enikankan ninu yin ko gbodo na owo nkan ija si omo-iya re, tori ko mo pe oseese ki esu (shayton) gba owo Oun ni yoo ba ko sinu ogbun ina." Won fenu kole Hadith yi lori. Gbolohun "ni yoo ba ko sinu ogbun ina" tumo si pe ni yio ba ko sinu ese eleyi ti yoo se okunfa ki owo ina.
Islam nfe awujo oni ifokanbale eyiti yoo rorun fun omoniyan ninu re lilo ati bibo latara ise sise ati igbiyanju ni orile Olohun. Nitori eleyi ni won fi odiwon iya lele ninu Islam tori ati gba owo eniti o ba ngbiyanju lati fowo abuku kan ifayabale tabi igunrege eto awujo Islam.
2. Ipese onje sinu ilu, eleyi laarin;
* ipese ise fun awon ti won ni ikapa sise ise lati le pese awon oun kosee moni ati awon oun ti won nfe fun won labe siseni loju kokoro ise sise. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: ki enikookan yin mu okun ki o wa fi gbe igi isepe seyin re, ki o wa ma ta, ki Olohun O wa fi gbe oju re kuro nibi ima bere lowo omoniyan, o loore fun un ju ki o mo toro lowo awon eniyan lo yala won fun un abi won ko fun un.
* Nina Owo ninu ile owo musulumi fun awon ti won ko le se ise nitori aini ikapa, abi ogbo, abi aisan, tabi eni ti won padanu ebi won. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe: eniti o ba fi owo sile "leyin iku re" fun awon ara-ile re ni, sugbon eniti o ba fi gbese abi awon omo sile, emi ni ni o fi sile fun, abi oranyan ni le mi lori, (nitoripe) emi ni alase " Waliyu" awon olugbagbo.
* Awon saara to je dandan fun awon alaini ni awujo musulumi. Won ni eto ninu owo zakati eyeti o je oranyan lori awon oloro ninu awon musulumi, eyiti o sepe oun ni ipa ise amojuto awujo ajosepo ninu Islam. Won yio gba Zakat lowo awon oloro ti won yoo si da pada si odo awon alaini nitori oro Ojise Olohun_ki ike ati ola Olohun ma ba- ti o so fun Muadh omo Jabal nigbati o gbedide losi ilu Yaman: Fi mo won pe Olohun se zakat ni oranyan le won lori ninu owo won, won yoo gba lodo awon oloro won, ti won yoo si da pada si odo awon talika won."
* Awon ore atinuwa, eleyi ti musulumi yio na sita pelu fi fe okan re lati gbo bukata awon omo ya re niti titele ase Olohun ati iwa iyonu Re. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe: enyin eniya! E mo fon salam ka, e si mo so okun ebi po, e si mo fun awon eniyan ni onje je, e si ma kirun ni ile (ni oru) nigbati awon eniyan nsun, e o wo Al-jannah pelu alafia." Tirimidhi logba wa, o si sope o ni alafia.
O tun sope: enikeni ti o ba mu adanwo kan kuro fun olugbagbo kan ninu awon adanwo aye, Olohun yoo mu kuro fun on na adanwo kan ninu awon adanwo ojo igbende, eni ti o ba se irorun fun eni ti nkan le fun, Olohun yoo se irorun fun on na ni ile-aye ati ni orun, eni ti o ba se idaabobo fun musulumi kan, Olohun yoo se idaabobo fun on na ni aye ati ni orun, Olohun yoo mo ran omoniyan lowo nigbakugba ti oun naa ba nse iranlowo fun omo-iya re." Muslim lo gba wa.
O tun so bayi pe: eni ti Olohun feran julo ninu eniyan ni eniti nse anfani julo, ise ti Olohun nife si julo ni idunu ti a mu ba musulumi, abi ki o mu kuro fun adawo kan, abi ki o ba gbe gbese re, abi ki o mu ebi kuro fun, ki nwa pelu omo-iya mi nitori bukata kan je oun ti mo nife si ju ki nse ikoraro osu kan ni mosalasi lo, eniti o ba se suru lasiko ibinu re, Olohun yoo se idaabobo si ihoho re, eniti o ba gbe ibinu kan mi ti o sepe ti o ba fe yoo se, Olohun yoo kun okan re pelu iyonu ni ojo igbende, eniti o ba lo pelu omo-iya re musulumi nitori atigbo bukata re titi o fi ba a gbo bukata na, Olohun yio fi ese re rinle ni ojo ti awon ese yio mo ye, dajudaju iwa buburu a mo ba ise je gegebi on ti o koro se mo nba oyin je.
* Ile ri iya ti o le koko fun eniti ki i ni akolekan si awon alamori awon omo-iya re musulumi. Ojise Olohun- ki ike at ola Olohun ma ba- so bayi pe: enikankan ninu yin ko ti di olugbagbo ododo titi yoo fi mo fe fun omo-iya re oun ti o fe fun ara re.
3. Ipese eko si inu re: Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" يَرْفَعِ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا مِنْكُمْ وَالَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ دَرَجَاتٍ"
Itumo: ".. Olohun yoo si se agbega ati iyi fun awon eniti won Gbagbo lododo ninu yin ati awo oni mimo…" Suratu-l-Hashr:11.
Eko kiko ni awujo Islam ki i se eto fun awon eniyan inu re nikan, bi ki i sepe o je oranyan le won lori. Ninu oranyan ni kiko eko ti won yoo fi se igbeduro awon alamori esin ati ile-aye, o si je dandan lori ilu-Islam ki o pese gbogbo irinse ti yoo je oluranlowo lati le se. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe: wiwa imo oranyan loje lori gbogbo musulumi."
Koda Islam ka sise igbiyanju lati wa imo; kiko nii ni imo ati kiko imo si oju-ona eyi tii sun ni losi Al-jannah. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: eniti o ba to oju-ona kan lati le wa imo, Olohun yoo se ni irorun fun pelu re oju-ona losi Al-jannah. Muslim logba wa.
Islam si tun ka dida owo bo imo ati imo mo se ifonka re ki won le se anfani latara re si ikan ninu oun ti won se leewo ti won si se ikilo ti o ni agbara lori re. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: " eni ti o ba fi imo kan pamo, Olohun yoo fi onde ina de enu re ni ojo igbende." Ibn Hibban so pe o ni Alafia.
4. Ipese irinse eto ilera, eleyi labe:
* Sise leewo gbogbo oun ti o ba lee ni ilapa lara ilera omoniyan, gegebi mimu awon oun ti npani lori, ati awon oun ti o le se akoba fun ilera. Olohun ti ola Re ga julo nso bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالْأَنْصَابُ وَالْأَزْلَامُ رِجْسٌ مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ"
Itumo: Enyin oni gbagbo ododo! Dajudaju oti ati tete tita ati orisa bibo, ati imo fi ofa pin kan, je egbin o si wa ninu ise esu, e jina si ki e le se orire." Suratu-l-Maidah: 90.
* Sise leewo jije eran oku nbete ati eje, ati eran elede. Olohun so bayi pe:
 " حُرِّمَتْ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةُ وَالدَّمُ وَلَحْمُ الْخِنْزِيرِ وَمَا أُهِلَّ لِغَيْرِ اللَّهِ بِهِ وَالْمُنْخَنِقَةُ وَالْمَوْقُوذَةُ وَالْمُتَرَدِّيَةُ وَالنَّطِيحَةُ وَمَا أَكَلَ السَّبُعُ إِلَّا مَا ذَكَّيْتُمْ وَمَا ذُبِحَ عَلَى النُّصُبِ وَأَنْ تَسْتَقْسِمُوا بِالْأَزْلَامِ ذَلِكُمْ فِسْقٌ"
Itumo: " Won se ni eewo fun yin eran ti o ku funra re ati eje ati elede, ati eyiti won pa lai pe oruko Olohun si, ati eyiti won fun ni orun pa, ati eyiti won lu pa, ati eyiti o re lule ti o ku, ati eyiti won kan pa, ati ajeku eranko ayafi eyiti e ba dunbu, ati eyiti pa fun orisa, ati ki e mo fi ofa pin kan, eleyi iwa poki.." Suratu-l-Maidah:3.
* Sise leewo awon iwa ti okan ko, gegebi iwa ibalopo laarin okunrin si okunrin, ati iwa agbere sina, ati ibalopo laarin obinrin si obinrin. Olohun ti ola Re ga julo nso bayi pe:
"وَلَا تَقْرَبُوا الزِّنَا إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَسَاءَ سَبِيلًا"
Itumo: " E ma se sunmo sina, dajdaju ohun ti okan ko ni, iwa ti ko dara ni." Suratu-l-Israi':32.
* Siso ati idabobo awujo pelu awon irinse iso ilera labe lilo gaga-idabobo ninu ilu abi nita ilu. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: " ti e ba gbo pe aisan ajakanle wa ni ilu kan, e ko gbodo wo be, ti o ba si sele ni ilu kan ti enyin si wa nibe, e ko gbodo jade kuro ninu re". Bukhari logba wa.
Nibi siso ara eni, ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: " alaisan kogbodo losi odo eniti o ni Alafia" Bukhari logba wa.
Gbogbo oun ti won so yii nibi pipese oun to je dandan je oun ti gbogbo omoniyan nwa, ojise Olohun-ki ike ati ola Olohunma a ba- so bayi pe: " eniti o ba moju ni ile re ni ifokanbale, ti o si ni Alafia ni ara re, ti onje ojo re nbe ni odo re, o da gegebi eniti won ko ile aye re jo fun un ni".

ISE DEEDE NINU ISLAM
Islam nse ise lati gbe igi di gbogbo oun ti o sepe o le mo fa isopinya ati eyemeya larin eniyan awujo musulumi, yala latara iran, tabi awo, tabi ileto, tabi ede. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَاءً
Itumo: " Enyin omo-enia e paya Oluwa yin eniti o se eda yin lati ara emi kan soso, ti o si se eda iyawo re lati ara re, ti o si tan opolopo okunrin ati obinrin lati ara awon mejeji…" Suratu Nisai:1.
Eleyi nitori ki awon ara awujo le maa gbadun pelu awon eto won ti o leto, ati ki enikookan won le mo ni igbonmo pelu deede, ko si awon eto adani fun ijo kan lori ijo miran. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe; " enyin eniyan eteti ki e gbo, dajudaju Oluwa yin eyokan ni, dajudaju baba yin eyokan ni, eteti ki e gbo! Ko si ajulo fun larubawa lori eniti ki i se larubawa, be si ni kosi ajulo fun eniti ki i se larubawa lori larubawa, be ni kosi fun alawo pupa lori alawo dudu, abi alawo dudu lori alawo pupa ayafi pelu iberu Olohun." Musnad Ahmad:23536.
Ipile iseda omoniyan ninu Islam eyokan ni, kosi aaye ninu Islam fun faari pelu onka ati iran lori imo fi enu iyepere ati abuku kan elomiran, ati imaa je eto won. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so pe: " Eyin eniyan! dajudaju Olohun ti mu kuro fun yin imaa se faari pelu igba aimokan, ati imaa se motomoto pelu awon baba re. Eniyan meji ni won je, oluse daradara olu paya Olohun, eni aponle lodo Olohun, ati olukoja ala eniburuku alai lasusi lodo Olohun. Omoniyan omo Adamo, Olohun seda Adamo lati ara epe…"
Kosi aye fun abosi ati faari larin omoniyan pelu awo ati iran, eleyi ni oun ti won npe ni asiko yi ni eyemeya iran. Awon yahudi ati Nasara ri ara won si pe awon ni ola lori omoniyan ti o ku. Olohun ti ola Re ga julo nse alaye paapa won, atipe gbogbo omoniyan lapapo bakanna ni won, ko si ajulo laarin won ayafi fi pelu iberu Olohun;
" وَقَالَتِ الْيَهُودُ وَالنَّصَارَى نَحْنُ أَبْنَاءُ اللَّهِ وَأَحِبَّاؤُهُ قُلْ فَلِمَ يُعَذِّبُكُمْ بِذُنُوبِكُمْ بَلْ أَنْتُمْ بَشَرٌ مِمَّنْ خَلَقَ "
Itumo: " Awon Yahudi ati Nasara nsope awa ni omo Olohun ati ololufe Re, so pe: ki wa ni o fa ti O fi nfi iya je yin pelu awon ese yin, sugbon eyin ko je nkankan ju ikan ninu awon eda Re lo…" Suratu Maida: 18.
Lati odo Magrur omo Suwaed to sope: mo ri baba Dhari Al-Gifaari ti o wo aso to rewa ti omo-odo re naa si wo aso ti o rewa "gegebi aso Abu Dhari", a wa bi leri pe ki lo fa. O so pe: emi bu arakunrin kan ni o ba lo fi ejo mi sun ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba – ni Ojise Olohun ba so fun mi pe; ire Abu Dhari; nje o bu pelu iya re bi? Ire je eniti iwa aimokan nbe lara re, awon eru yin omo-iya yin ni won je, Olohun gbe won si abe yin, enikeni ti omo-iya re ba wa labe ikapani re ko ya fun un je ninu oun ti on je, ki o ma fun un wo ninu oun ti on ba wo, ki e si ma mo la bo won lorun oun ti won ko ni ikapa. Ti e ba wa la bo won lorun oun ti won ko ni agbara re e ran won lowo lori re." Bukhari logba wa.
Bakanna ni ni abala ijosin omoniyan bakanna ni won, olowo, talika, oludari, omo eyin, alawo funfun, alawo dudu, eni abiyi, ati eni eyin. Kosi awon ijosin kankan abi ase, abi iko fun ni Kankan ti won je adayanri fun ijo kan lori ijo miran, gbogbo eniyan bakanna ni won lodo Olohun. Olohun so bayi pe:
مَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِنَفْسِهِ وَمَنْ أَسَاءَ فَعَلَيْهَا وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ
Itumo: " Enikeni ti o ba se daada o se fun emi ara re, eniti o ba si se aburu o se fun lori ara re, Oluwa re ki se alabosi si eru (re)." Suratu Fusilat:46.
Ni abala si se idajo ofin Sharia ati lilo awon ilana idiyaje ti o ni odiwon gbogbo eniyan bakanna ni won, ko si idiyaje ti o je adayanri fun awon kan lori awon miran, ko si ije igbadun fun awon kan laisi isiro ati ayewo fun won lori awon miran. Lati odo Ai'sha- ki Olohun O yonu si – o ni awon iran Quraeshi ko airoju nipa arabirin Makhzumiyah eyiti o jale, won ba sope: taani yoo ba ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba – soro nipa re? Won ba sope: ko si eniti o ni ikapa ati sebe ayafi Usama omo Zaydi ti o je ololufe onse Olohun, ni Usamah naa ba lo ba ojise Olohun. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba – ba sope: n je iwo yoo mo se isipe nibi enu ala ninu awon enu ala Olohun bi? Ni Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- ba dide ni eniti o nse khutuba, ni o ba sope: dajudaju on ti o se okunfa iparun fun awon ti o saju yin nipe ti eni abiyi ba jale ninu won, won yoo fi sile, ti ole (eniti ko ni ipo) ba jale ninu won, won yoo se igbeduro iya fun, mo fi Olohun bura, ti Fatimo omo Muhammad ba jale emi yoo ge owo re." Al-Bukhari:2388.
Ni abala jije anfani nibi oro ilu, gbogbo eniyan bakanna ni won (itumo eleyi nipe oun ti won ba pin laarin awon ara inu musulumi ninu oro ile owo musulumi) ki i se itumo pe oun ti omoniyan ngba di po oun ti won se ni ise, toripe iyato je oun ti o le sele ti ko si iyemeji nibe. Eleyi ni Abu-bakr As-sidiq arole akoko fun Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba – ti o npin ebun laarin awon musulumi pelu deede, won ba so fun pe: Ire arole Ojise Olohun o pin owo yii laarin awon eniyan dogban dogba, o si je okan ninu awon ti o wa ni ipo ola ati awon ti o koko wo inu Islam, yoo dara ti o ba gbe ola fun awon eniti won wa ni ipo ola ati awon eni akoko ninu Islam? Abu-bakr si fesi pe: eyiti e so kale yii nipa ipo ola ati sisiwaju nibi wiwo inu esin Islam ko je nkankan lodo mi, eleyi esan re nbe lodo Olohun, sugbon eleyi oun aye ni, sise deede nibe loore ju gbigbe ola fun awon kan nitori sisiwaju won wo inu Islam, awon eniti won si se fun Olohun, esan won nbe lodo Olohun, sugbon owo eleyi je oun ipin fun enirere ati eni buburu, ki i se esan fun ise won" Al-Ahkam As-Sultaniyyah (Abi Yaa'la)
Gbogbo enikookan ninu awon ara awujo Islam loni eto sise anfaani ninu ebun ati oun ti Olohun pese re si inu-aye ninu awon oun alumoni, o si je dandan lori ilu Islam lati pese ati sise eto jije anfani ninu awon alumoni yii ti ko ni je pe awon apakan ninu awon ara-inu ni won yio mo se anfaani pelu re ti won yoo si moo k o si abe pelu pe won yoo mo se idajo isemi aye awon eniyan. Olohun so bayi pe:
" هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ ذَلُولًا فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِنْ رِزْقِهِ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ
Itumo: " Oun ni eniti O te ile fun yin, nitorina ki e ma rin ni agbegbe re ki e si ma je ninu awon ese re, odo Re si ni iseri pada gbogbo eda." Susatu Mulki: 15.
Atipe Islam ni abala omonyina ati gbigbe won tobi nma se deede larin gbogbo omoniyan, kosi iyato, opinya, ati ijegaba, sugbon ni abala awon alamori esin opinya wa laarin awon ara awujo, eniti o se ise o yato si oroju, enirere yato si eni buburu. Olohun so bayi pe:
" وَلِكُلٍّ دَرَجَاتٌ مِمَّا عَمِلُوا وَمَا رَبُّكَ بِغَافِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ
Itumo: " Enikookan ni yoo gba esan ohun ti won se nise, Oluwa re ko gbagbe Ohun ti won se" Suratu An'am: 132.


ISLAM ATI SISO AWON OHUN TI O JE DANDAN..
Islam wa lati pe awon ofin ti o wa lati sama (odo Olohun) eyiti won saju re, bakanna ojise Olohun Muhammad- ki ike ati ola Olohun ma a ba- je opin awon ojise ati awon Anabi- ki ola Olohun ma a ba won- ti won saju re. Islam nse igbiyanju gegebi awon ofin sama ti o siwaju se se igbiyanju lati pese ati lati so awon ohun ti o pandandan lati le se ifidimule fun aye ati ilosiwaju re. O nse igbiyanju losi ibi:
1.    Idabobo fun esin:
Esin je ohun adiokan eyeti oduro lori awon ipile eyiti nseto isemi awon omoniyan ati awon awujo. O wa ninu awon adiokan yii eyiti o je ti emi lasan, o si nbe ninu re eyiti o yapa si adamo ati lakaye ti o dara ti adun ti o han yoo si se atako re. Mo gba lero pelu re awon adisokan eyiti npepe losi ibi ima gbe iyi ati ijosin fun awon eda, gegebi Olohun se fun wa ni iro nipa won pelu oro Re bayi pe:
" وَاتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ آلِهَةً لَا يَخْلُقُونَ شَيْئًا وَهُمْ يُخْلَقُونَ.."
Itumo: Atipe won mu nkan miran ni oluwa leyin Olohun ti won ko le se eda nkankan ti awon naa si je oun ti won da.." Suratu Furqani:3.
Atipe nbe ninu awon adisokan yii eleyi ti o je itele ife inu ati eto adamo, eyi je adisokan yodoyindin aye ti o gbe ola fun yoyoyindin aye, ti o si ti gbogbo ohun ti o ba yato si danu, gegebi Oluwa wa se fun wa niro nipa re pelu oro Re to lo bayi pe:
" أَفَرَأَيْتَ مَنِ اتَّخَذَ إِلَهَهُ هَوَاهُ..."
Itumo:" Nje ire ti ri eniti o fi ife-inu re se Olohun re…." Suratu Jathiyah: 23.
Lara awon adisokan yii ni eyiti o se pe o je ti emi ati ara, eleyi ni esin Islamu, eyi ti o sepe ko se opinya laarin emi ati ara, bikosepe o se odinwon laarin won pelu pe ko se idowobo eto apakan nitori apa miran, awon ase re ntoka lori sise amojuto emi gegebi bi o se npani ni ase ise amojuto ara, awon iko funni re naa si nko ise ifowoyepere mu emi gegebi bi nse ko gbogbo ohun ti o ba le ko suta ba ara. Olohun so bayi pe:
" وَابْتَغِ فِيمَا آتَاكَ اللَّهُ الدَّارَ الْآخِرَةَ وَلَا تَنْسَ نَصِيبَكَ مِنَ الدُّنْيَا وَأَحْسِنْ كَمَا أَحْسَنَ اللَّهُ إِلَيْكَ "
Itumo: " Mo wa orun pelu oun ti Olohun se fun o ni ile-aye, ma si se gbagbe ipin re ni ile-aye, ma se daada gegebi Olohun se se daada si o…" Suratu Al-Qasos: 77.
Olohun tun so bayi pe:
" رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الْآخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ
Itumo: " Ire Oluwa wa fun wa ni daada ni aye ati ni orun, si la wa kuro nibi iya-ina" Suratu Baqarah: 201.
Nigbati o je pe Islam je esin ati ilu, oun ni esin ti Olohun yonu si fun omoniyan lapapo lati le je opin awon esin, oun ni esin aarin meji eleyi ti o sepe ko yapa si adamo be si ni ko se atako re. O je dandan lorun awujo eleyi ti o gba Islam ki o maa so o pelu ki o si maa se igbiyanju ipepe si inu re ati ima fi daada re mo awujo nibi oro ti o dara, ati ibalo gidi eleyi ti esin ati adisokan re npepe si i niti itele ase Olohun ti o so bayi pe:
" وَقُولُوا لِلنَّاسِ حُسْنًا وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ "
Itumo: " E si maa so oro ti o dara si omoniyan, ki e si maa gbe irun duro, ki e si maa yo Zakat.." Suratu Baqarah:83.
Koda awon ipile Islam paapaa npepe si siso lati ara oun ti o ko sinu ninu awon ipile daada ati deedee ati ife ati ike eleyi ti yoo mu wa awujo ti o dara, ati eleyi ti gbogbo eniyan nsare lati se amuse re ati sise isemi labe iboji re.
Lara awon irinse siso esin nipe Islam:
*O npase fun awon olutele re ima se amojuto re latara ima se ifihan daada re pelu jijina si ikoja ala ati ile koko, tabi fifi owo dengbere mu u, nitori oro Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- ti o so bayi pe: Olohun ko gbe mi dide ni olu le koko ati ni olu le koko mo ni, sugbon O gbe mi dide ni olukoni, olu se irorun. Muslim logba wa.
* O pa awon olutele re lase ki won jinna si igbedide ota fun esin Islam lati ara ima je awon eniyan nipa si inu re nitori Oro Olohun to so bayi pe:
" وَقُلِ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكُمْ فَمَنْ شَاءَ فَلْيُؤْمِنْ وَمَنْ شَاءَ فَلْيَكْفُرْ إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلظَّالِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمْ سُرَادِقُهَا.."
Itumo: " Wipe: Otito lati odo Oluwa yin ni o ti wa; nitorina eniti o ba fe ki o gbagbo eniti o ba si fe ki o se aigbagbo. Dajudaju Awa ti pese ina fun awon alabosi, ogba re yoo rokirika won…" Suratu Kahf: 29.
* O pa awon olutele re lase pe ki won ma ma kanju lati ri ere ipepe awon alaigbagbo si inu Islam. Olohun so bayi pe:
" إِنَّا أَنْزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ لِلنَّاسِ بِالْحَقِّ فَمَنِ اهْتَدَى فَلِنَفْسِهِ وَمَنْ ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا وَمَا أَنْتَ عَلَيْهِمْ بِوَكِيلٍ
Itumo:" A wa ni aso tira kale fun o si awon eniyan pelu ododo, eniti o ba mona fun ori ara re ni, eniti o ba si sina, o sina fun ori ara re, iwo ki i se oluso le won lori" Suratu Zumar: 41.
* O pa awon olutele re lase idunnimo awon eko esin eleyi ti won npe awon omoniyan si ati lati mo se imulo re ni ti fifi ise se lati le je oun iso ati ireni fun awon awujo ti nbo, bakanna ki o le je oun ipepe sinu re, latara ilapa awon eko re lara awon olutele re, eleyi ti npepe lo sibi awon iwa ti o dara. Nitori eleyi ni Olohun ti ola Re gbongbon fi fi enu ate lu oluyapa si awon iwa yi. Olohun so bai pe:
" أَتَأْمُرُونَ النَّاسَ بِالْبِرِّ وَتَنْسَوْنَ أَنْفُسَكُمْ "
Itumo: " Nje e o ma pa awon eniyan ni ase daada bi ti eyin si gbagbe ara yin" Suratu Bakora:44.
* O pa awon olutele re lase ima se ike si awon omoniyan lapaapo, nitori oro ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- to so bayi pe: awon olukeni Olohun Oba " Ar-Rahmon" yio ke won, e ma ke awon oun ti nbe lori ile Eniti nbe ni sanmo yoo ma ke eyin naa" Ahmad, Abu Daawud, ati Tirmidhi ni won gba wa. Al-Baani so pe oni Alafia.
Bakanna ni ima fe daada fun awon omoniyan ni apaapo, nitori oro ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba a- to so bayi pe: ma fe fun omoniyan oun ti o fe fun ara re, o je musulumi" Tirmidhi logba wa
* Ipese esan nla lori fi fi esin Islam mo omoniyan ati pipe won sinu re, nitori ki won le ma je igbadun latara eko re pelu ifokanbale awujo ati ifayabale emi eleyi ti gbogbo omoniyan nsare fun. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe: ki Olohun fi enikan mona lati owo re o loore fun o ju rakunmi pupa lo" (Rakunmi pupa je ohun iyebiye oro larubawa).
Ki a lo mo pe siso esin je okan ninu awon eko eleyi ti gbogbo esin to saju fi enu ko le lori.

2.    Idabobo fun emi:
Nipaapa emi omoniyan ninu Islam je oun abiyi, oun iyebiye, oun ti ipo re iso ti o lagbara si ni. Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun ma ba – so bayi pe: mo fi eniti emi mi nbe lowo re bura pe pipa onigbagbo ododo kan tobi lodo Olohun ju ki aye o pare lo". Ibn Majah logba wa, Al-Baani sope Hadith ti oni Alafia ni. Saheehu Jaami': 5078 ati Saheehu At-Targeeb Wa Tarheeb: 2438.
Islam nse idaabobo fun emi omoniyan, ninu re:
* Sise idabobo fun emi omoniyan kuro lowo suta elomiran, nitori eleyi ni won fi se ofin igba-esan (Kisoosi) ninu Islam. Won pa ase pipa apaniyan ti o momo pa elomiran, ti awon ebi eniti won pa ko ba se amojukuro fun un. Sugbon eniti o pa elomiran niti asise, idajo ti re ninu Islam ni sisan owo eje ati itanran eyi tii se oun siso eru kan di omoluwabi. Eniti ko ba ni agbara eleyi, yio gba awe osun meji ni tele-ntele, ti ko ba tun ni agbara re, yoo fun ogota alaini ni onje. Eleyi ko je nkankan jupe lati se idabobo fun emi ati iso fun isemi awon omoniyan kuro nibi ima se aburu pelu re ati lati je ideruba fun awon alaburu kuro nibi imaa da ese ipaniyan.
 Nitoripe eniti o ba mo pe ti oun ba pa eniyan won yoo pa oun naa, yoo kora duro, yoo si jawo kuro nibi aburu re. Ti ko ba jepe iya apaniyan ni pipa ko ni si ijawo kuro nibi aburu ati sise re. Ki o woye lori eleyi si gbogbo awon iya oni gbeedeke eleyi ti Islam fi ala si won, o je oun igbeni jina si aburu, won ko si gbe won kale ayafi nitori ati se idabobo fun omoniyan ati iso fun awon eto re. Olohun so bayi pe:
وَلَكُمْ فِي الْقِصَاصِ حَيَاةٌ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ
Itumo: " Isemi mbe fun yin nibi igbesan enyin ti eni lakaye, ki e le ba sora yin" Bakora:179.
Islam kofi ma lori awon idiyaje ile-aye yi nikan, bikosepe o ti se igbekale lori imoomo paniyan iya orun eleyi ti nse ibinu Olohun ati iya Re ti o le koko ni orun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَمَنْ يَقْتُلْ مُؤْمِنًا مُتَعَمِّدًا فَجَزَاؤُهُ جَهَنَّمُ خَالِدًا فِيهَا وَغَضِبَ اللَّهُ عَلَيْهِ وَلَعَنَهُ وَأَعَدَّ لَهُ عَذَابًا عَظِيمًا"
Itumo: " Eniti o ba pa olugbagbo lododo kan ni ti amo mo pa, esan re ni ina Jahanam ti yoo se gbere ninu re, ibinu Olohun yoo je ti e ati ibi dandan Re, O si pese de iya nla" Suratu Nisai:93.
* Ise iso omoniyan kuro lowo emi re ti ma npase aburu. Oun ti o pan dandan fun omoniyan lori eleyi nipe dajudaju Islam ti se ni dandan fun un lati ni akolekan awon ohun ti nbo wonyi;
a. imoomo doju re ko oun iparun, nitoripe ki i se nkan ini re, bi ki i sepe omoniyan je oluso fun un lati odo Olohun Oba to gbongbon. Islam se pipa ara eni leewo nitori oro Olohun ti ola Re ga julo ti o sope:
" وَلَا تَقْتُلُوا أَنْفُسَكُمْ إِنَّ اللَّهَ كَانَ بِكُمْ رَحِيمًا "
Itumo: "E ma se pa ara yin, dajudaju Olohun je Onike fun yin" Suratu Israi':29.
b. Imo fun un ni awon eto re eleyi ti Olohun se ni ofin, ko si leto lati maa se abosi re gegebi imaa se ni eewo fun un oun ti Olohun se leto fun un nibi jeje, mimu, wiwo, ati igbeyawo, nitori oro Olohun ti ola Re ga julo ti o so bayi pe:
" قُلْ مَنْ حَرَّمَ زِينَةَ اللَّهِ الَّتِي أَخْرَجَ لِعِبَادِهِ وَالطَّيِّبَاتِ مِنَ الرِّزْقِ "
 Itumo: Sope; tani eniti o se leewo oso Olohun eleyi ti O mu jade fun awon erusin Re ati awon ohun ti o dara ni ipese.." Suratu A'raf:32.
Sugbon igbadun pelu awon ohun ti o dara yi gbodo wa nibamu si awon enu ala eleyi ti sharia fi lele, pelu jijina si ina apa, ahun ati igberaga, ni ibamu si oro Olohun ti ola Re ga julo ti O so bayi pe:
" وَكُلُوا وَاشْرَبُوا وَلَا تُسْرِفُوا إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِين "
Itumo: " E ma je ki e si ma mu, ki e si ma malo ilo apa, dajudaju On Olohun ko nife awon onilokulo" Suratu A'raf: 31.
Ko leto ninu esin Islam lati maa fi iya je ara ati aini amojuto re koda ko sepe loju ponna ijosin ni.
 Lati odo Anas omo Malik-ki Olohun yonu si- o sope: awon arakunrin meta kan wa si ile ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma ba- ni eniti nbere nipa ijosin re, nigbati won fun won niro nipa ijosin re won fi oju kere ijosin won si ijosin re, won wa sope: ki ni ipo wa si ipo ojise Olohun, eniti o sepe nipaapa won ti fi ori-ese re ti o siwaju ati eyiti nbo jin, enikan ninu won ba sope: e ri emi maa ma kirun ni gbogbo ale titi lailai, enikeji ninu won si sope; e ri emi maa ma fi gbogbo odun gba awe mi o ni sinu, ni eniketa ba dahun wipe: e ri emi ma jina si awon obinrin mi o ni se igbewayawo. Bayi ni ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- ba wa ba won, O ba sope: eyin ni e sope bayi bayi? Ee ri, mo fi Olohun bura pe emi paya Olohun ju yin lo, mo si beru Re ju yin lo, sugbon mo ma nkirun mo si ma nsun, mo ma ngba awe mo si ma nsinu, mo si nfe iyawo, eniti o ba gunri kuro nibi ilana mi ki i se ara mi" Sahih Bukhari: 4776.

3.    Idabobo fun lakaye:
Lakaye ninu Islam je mojemu ilabo lorun ati ojuse, nitori eleyi ni Islam fi se leewo gbogbo ohun ti o le je okunfa ipalara yala labe mimu awon oun ti o ma npa ni lori tabi awon ti ma nfa ihunrira. Islam ma npe oti ati gbogbo ohun to bajo ni iya egbin nitori titobi aburu eyi to nbe nibi dide idi re, nitori re ni o fi pase nina olude idi re ki lakaye le ma be ni Alafia, ati lati se idabobo fun ije omoluwabi ati owo. Yoo wo inu ipalara yii awon irori aburu sinu lakaye eleyi ti won yoo ma pepe losi gbogbo oun ti ko dara ati ibaje. Olohun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالْأَنْصَابُ وَالْأَزْلَامُ رِجْسٌ مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ * إِنَّمَا يُرِيدُ الشَّيْطَانُ أَنْ يُوقِعَ بَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ فِي الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ وَيَصُدَّكُمْ عَنْ ذِكْرِ اللَّهِ وَعَنِ الصَّلَاةِ فَهَلْ أَنْتُمْ مُنْتَهُونَ "
Itumo: Enyin onigbagbo ododo! Dajudaju oti ati tete tita ati orisa bibo, ati imo fi ofa pin kan, egbin ninu ise esu ni, e jina si ki ele se orire. * Esu ngbero lati da ota ati ikorira sile larin yin nibi oti ati tete-tita ati lati ko di yin kuro nibi iranti Olohun ati irun kiki, e ki yio wa siwo" Suratu-l-Maidah: 90-91.
Atipe ki Islam le kodi re ninu awujo ni o fi se leewo sise re abi kiko arisiki jo lati ara re abi iranlowo lori titan ka re, nitori oro ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- to so bayi pe: won sebi le oti ni oju panna mewa; oti gangan fun ra re, eniti o nse oti, eniti o nse fun tita, eniti o nta oti, eniti o nra a, eniti o ngbe e, eniti won gbe loo ba, eniti o na owo oti, eniti o nmu u, ati olu po lowo re" Ahmad ati Ibn Majah logba wa, Al-Banni ni o ni alafia.

4.    Idabobo fun omoluwabi:
Islam se lewo gbogbo ohun to le ko abuku ba omoluwabi musulumi yala eyiti o han abi eyiti pamon. O se ni eewo;
 a. Sina sise, Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" وَلَا تَقْرَبُوا الزِّنَا إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَسَاءَ سَبِيلًا "
Itumo: " Atipe ki e ma se sunmo agbere (sina), dajudaju o je ohun ti kodara. O si buru ni oju ona". O se lewo gbogbo ohun to le je okunfa kiko si inu re:
* Gegebi ima fi owo pa obinrin ti ki se eleto eni lara ati ima fi enu ko enu re. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: " gbogbo omo Adam ni yoo ko si inu sina laisi ibuye, oju; sina re ni wiwo, owo; sina re ni ima fi owo pani lara, emi yoo ma fa si, ti abe yoo si so di ododo abi ki o pe ni iro" Ahmad ati Ibn Hibban ni ogba wa. Itumo Hadith yi nipe dajudaju won ti pebubu ipin omo Adam nibi sina, o nbe ninu won ti sina re yoo je tooto pelu titi abe bo abe eyiti o je eewo, o si wa ninu won eyi ti sina re yoo je adape nibi mima wo eewo, ati ima teti gbo sina, ati oun ti o le se okunfa re, abi ima fi owo pa obinrin ti kii se eleto eni lara, abi fenu ko lenu, abi ririn lo bi sina, abi wiwo o, abi oro ti ko leto pelu obirin ti ki se eleto eni, ati awon ti o jo.
* Abi ima wa pelu obinrin ni koko laisi alagata. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: okunrin Kan ko gbodo wa pelu obinrin ni koko ayafi pelu alagata. Arakunrin kan ba dide, o ba sope: Ire ojise Olohun; iyawo mi jade lo si haji, emi si ti ni ipinu jijade losi ogun bayi bayi? Ojise Olohun sope: pada, lo se haji pelu iyawo re" Bukhari ati Muslim. Alagata ni oko obinrin ati awon ti ko leto fun lailai lati fe ninu ebi gegebi egbon abi aburo re, abi egbon tabi aburo baba re, abi pelu okunfa ti o leto gegebi awon ti won se leewo pelu ifunni loyan.
* Abi ima wo ohun ti ko leto lati mo wo. Olohun so bayi pe:
قُلْ لِلْمُؤْمِنِينَ يَغُضُّوا مِنْ أَبْصَارِهِمْ وَيَحْفَظُوا فُرُوجَهُمْ ذَلِكَ أَزْكَى لَهُمْ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا يَصْنَعُونَ * وَقُلْ لِلْمُؤْمِنَاتِ يَغْضُضْنَ مِنْ أَبْصَارِهِنَّ "
Itumo: So fun awon olugbagbo lododo pe ki won re oju won sile, ki won o si so awon abe won, eleyi loore fun won. Dajudaju Olohun ni imo pelu oun ti won nse. * Atipe so fun awon olugbagbo lododo lobinrin pe ki won re oju won sile.." Suratu Nur: 29-30. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so fun Ali bayi pe: Ire Ali! Ma ma fi wiwo tele wiwo, dajudaju alakoko je ti e (toripe ki i se pelu a momo se), elekeji kii se ti e (toripe pelu a momo se re, nitorina yio je ese fun o)" At-tirmidhi ati Abu Dawood ni o gba wa, Al-Banni so pe o ni Alafia.
b. Bakanna ni Islam se ni eewo imaa leni ni oko aburu eleyi ti a mo si "Al-Kadhfu" nitori ati se idabobo fun omoluwabi eniyan. Eniti o be kefin si enikan yala lokunrin tabi lobinrin pelu awon isesi ti ko ba iwa omoluwabi mu, ti ko wa le se afirinle re pelu awijare won yoo gbe ijiya olukefin le lori, eleyi si ni nina ni ogorin egba nitori oro Olohun ti ola Re ga julo ti o so bayi pe:
" وَالَّذِينَ يَرْمُونَ الْمُحْصَنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَأْتُوا بِأَرْبَعَةِ شُهَدَاءَ فَاجْلِدُوهُمْ ثَمَانِينَ جَلْدَةً وَلَا تَقْبَلُوا لَهُمْ شَهَادَةً أَبَدًا وَأُولَئِكَ هُمُ الْفَاسِقُون "
Itumo: " Awon ti won npe pansaga mo awon obinrin ti won kii se oni pansaga, leyinna ti won ko si ri eleri merin mu wa, e na won ni ogorin egba e ko si gbodo gba ije ri won lailai, awon eleyi ni poki." Suratu Nur: 4.
Gegebi Islam se se ni eewo nitori ati se idabobo fun omoluwabi eniyan, gbogbo oro abi ise ti o le ko alebu ba iyi omoniyan, ati iroyin re ti yio si so ni o ko bu. Olohun ti ola Re ga julo to so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا يَسْخَرْ قَوْمٌ مِنْ قَوْمٍ عَسَى أَنْ يَكُونُوا خَيْرًا مِنْهُمْ وَلَا نِسَاءٌ مِنْ نِسَاءٍ عَسَى أَنْ يَكُنَّ خَيْرًا مِنْهُنَّ وَلَا تَلْمِزُوا أَنْفُسَكُمْ وَلَا تَنَابَزُوا بِالْأَلْقَابِ بِئْسَ الِاسْمُ الْفُسُوقُ بَعْدَ الْإِيمَانِ وَمَنْ لَمْ يَتُبْ فَأُولَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ * يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيرًا مِنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ وَلَا تَجَسَّسُوا وَلَا يَغْتَبْ بَعْضُكُمْ بَعْضًا أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَنْ يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتًا فَكَرِهْتُمُوهُ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَحِيمٌ "
Itumo: Eyin ti e gbagbo lododo! Ki ijo kan mase maa fi ijo kan se yeye, o le je pe won dara ju won lo, ki awon obinrin ma se ma se yeye awon obinrin o le je pe won dara ju won lo, e ma se ma bu ra yin e ma se ma pe ara yin ni oriki buburu, aidara ni oruko buburu je leyin igbagbo, eniti ko ba ronupiwada awon eleyi ni alabosi * Eyin ti e gbagbo lododo! E jina si opolopo abadida, dajudaju apakan abadida je ese, e ma se mo to pinpin ara yin, ki apakan yin ma se maa pegan apakan leyin. Nje okan ninu yin yoo nife lati je eran omo iya re ni okunbete bi? Eyin korira eleyi, e paya Olohun, dajudaju Olohun je Olugba-ironupiwada Onike" Suratu Hujuraat: 11-12.

5.    Idabobo fun owo:
dajudaju Islam mo gaga ti o nipan yi dukia omoniyan ka, eleyi labe fifi iya ti o le koko lele lati le so o kuro nibi fifi owo abuku kan an. O fi rinle ijiya gige owo ole ki o le je idabobo fun dukia. Olohun so bayi pe:
" وَالسَّارِقُ وَالسَّارِقَةُ فَاقْطَعُوا أَيْدِيَهُمَا جَزَاءً بِمَا كَسَبَا نَكَالًا مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ "
Itumo: " Ole lokunrin ati lobinrin e ge owo awon mejeji ni esan fun ohun ti won se, idiyaje lati odo Olohun, Olohun je Alagbara Ologbon" Suratu Maida: 38.
Gige owo kii se pelu aisi awon onde gegebi awon ti ko mo nipa Islam se lero, o ni awon mojemu eleyi ti o je dandan ki a ri ki o ti di pe won yoo ge owo, leyi ti o se pe ti a ba se afeku majemu kan, abi ti iruju ba wa lara re, won ko ni se amuse gige owo. Awon majemu naa niwonyi:
a. ki owo naa wa ni aye to pamo ki o wa lo fo o, sugbon owo ti o han si gbogbo oju ti ko pamo fun enikankan ti o si je eyiti won fi pamo a ko ni ge eniti o ba ji lowo, sugbon iya ikoni leko wa fun irufe eniti o ba ji iru owo bayi lati le je odi idabobo fun dukia awon eniyan, nitoripe eniti o ni owo yii se ateewo ni asiko yii pelu aifi owo naa pamo si aaye owo.
b. ki o ma jepe bukata jije abi mimu ni o ti ni opanpan ti o fi jale. Ti o ba je be, ko si igeni ni owo, nitori sise bee Umar- ki Olohun yonu si- ni odun oda. Won pe ni odun oda nitori isele iberu ati ebi ti o sele nibe.
c. ki owo ti o je jiji pe odiwon ti won gbe kale fun owo gige. Sugbon eyiti o ba kere si, kosi gige owo nibe. Ki o wa di mimo fun wa pe ijiya yii ati eyiti o yato si ninu awon aala idiyaje ninu Islam koni di amuse ayafi nigbati gbogbo iruju ba kuro lara re, toripe idiya jeni koni waye nigbati iruju ba wa nitori anfani eniti a kefin si.
    Sugbon shariah gbe kale pe nigbati aala idiyaje ba wo nitori bibe iruju, (idiyaje ikodi), nigbanaa idiyaje ikoni leko yoo fi di mule. Eleyi ni idiyaje ti o kere si aala idiyaje ti adajo yoo fi rinle, ti lile koko re ma nyato si ara won pelu bi iwa ese ati odaran ba se ri. O le je pelu itimole, abi nina, abi ikoni leko (Ta'ziri), abi owo itanran, ati beebee lo ninu ohun ti adajo ba ri pe o se deedee pelu odaran.
Bakanna ni Islam se lewo gbogbo ohun ti o je ikoja aala lori dukia owo gegebi jija gba pelu agbara, ati gige ile awon eniyan ni ona aileto, abi gbigba owo won ni ona ti koba ofin mu rara gegebi iyanje ati owo eyin. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
"وَلَا تَأْكُلُوا أَمْوَالَكُمْ بَيْنَكُمْ بِالْبَاطِلِ "
Itumo: " E ma se je owo yin laarin ara yin pelu ibaje" Suratu Bakora: 188.
Olukoja ala lori awon dukia yii ni ona aileto bukata si iya ti ole koko ni ojo igbende nitori oro Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- to so bayi pe: eniti o ba gba owo omoniyan musulumi kan ni ona aileto yoo pade Olohun Oba nla ni Eniti yoo ma binu si." Ahmad, Bukhari, Muslim, ati At-Tirmidhi ni won gbaa wa.
Islam se idapada nkan ti olugba nkan elomiran pelu agbara jagba ni oranyan. Ti o ba ti ba nkan naa je, abi o ti lo, won yoo pa ni dandan fun pe ki o san odiwon nkan naa, sugbon ti eniti o ni nkan ba yonda re, nigbana eto yoo kuro lorun re, sugbon won yoo je ni iya ikodi niti ikoni ni eko.
Koda Islam se leto fun eniti o ni dukia lati se idabobo fun dukia re pelu gbogbo ona ti o rorun koda ko sepe yoo de ipo pipa eniti o fe se aburu si dukia re laini gba esan lara re. Sugbon ti idakeji ba sele ti eniti o fe fi tipatipa gba dukia re ba paa, nigbana oun yoo je eniti o ku si oju-ona Olohun (Sha'eed) nitori oro Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- to so bayi pe: " eniti won ba pa nitori owo re yoo je Sha'eed" Bukhari logba wa: 2348.
Ohun Ti A ri ni Oju Ona Ti A Mu (Al-Luqot) ninu Islam
Islam wa pelu awon ofin eleyi ti o sepe nso awon owo apapo gegebi o se nso awon owo adani, sugbon oun ti o kan wa nibiyi ni awon eto eleyiti o sopo mo dukia. Dukia ninu Islam je nkan owo ati abiyi ti ko leto lati fi abuku kan an koda ni akoko ti o sonu. Kii se gbogbo dukia ti o sonu ni o je eto fun eniti o ri, bi kii sepe awon onde wa fun amojuto re. Ninu awon ofin Islam eleyi ti o gbekale ni abo fun dukia aladani ni; ofin oun ti a ri he ati oun ti o sonu. Eleyi je okan ninu awon ofin ti Sharia Islam fi yato si gbogbo ofin miran. Al-Luqotu ni oun ti won ri he ninu dukia ti won ko si ma eniti o ni. Won ma nlo Luqatu fun owo ati oun ti o joo, bakannaa won ma nlo fun eranko " Da'alah" eleyi ti o ntunmo si oun ti o sonu.
Islam se mimu oun ti a ri he leto nigbati o ba wa ni aye ti a ko ni ifokanbale le lori, yala nitoripe won le jii tabi ki won baje , eleyi kii se nitori nkankan bikosepe lati se idabobo fun dukia omoniyan kuro nibi bibaje ati lati le se idapada re si odo eniti o nii ti o ba je eni mimo, nitori oro Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- ti o so fun okunrin ti o wa si odo re ni eniti nbere nipa Al-Luqat (ohun ti a ri he); o sope: mo kerengbe re ati okun re, leyinna fi wa elo fun odun kan, ti eniti o ni ba wa da pada fun un, sugbon ti ko ba wa o di ti e. O sope (arakunrin to wa ba ojise Olohun): bawo ni ti agutan ti o sonu? O sope (ojise Olohun): ninu ki o je tire, abi ko je ti omo iya re, abi ko je ti ikoko. O sope (arakunrin naa): bawo ni ti rakunmi? O sope (ojise Olohun): ki ni tie pelu re? o wa pelu re ife re ati patako re atipe o ma nlo si ibi omi (lati mu omi lai sepe won mu lo si ibe), o si ma nje ninu koriko ti ti yoo fi pade olowo re" Bukhari ati Muslim.
Eleyi fun awon nkan ti kii se nkan ti ko niye lori ati nkan jije. Sugbon ti o ba je nkan jije, ki se oranyan lati se ifilo re, o si leto lati se anfani pelu re ati lati je e. Anas omo Malik- ki Olohun yonu si- sope: Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- re koja pelu eso tamuru ni oju ona, o ba sope: ti ki ba sepe mo nberu ko ma je sara mi o ba je e" Bukhari ati Muslim. (nitoripe Olohun se leewo fun un lati gba sara).
Bakanna awon ohun ti o ba je nkan ti ko niye lori ti ko ni asunsi, o leto fun eniti o ba mu (ri) lati se anfani pelu re nitori Hadith Ali-ki Olohun yonu si- pe: oun lo si odo Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- pelu owo dinaru eleyi ti o rihe ni oja. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma ba- wa sope: fi welo fun ojo meta. O se bee, sugbon ko ri eniti o ni. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si so fun pe: je." Sahih sunan Abi Dawood.
O leto fun eniti o mu nkan ti o ri he lati se sara pelu re ni aniyan eniti o nii, abi ki o se anfani pelu re leyin ti odun kan ti re koja ni eniti ti o fi nwelo sugbon ti ko mo eniti o nii, nitori Hadith Aos omo Ka'b ti o sope: mo ri apo ifowo pamo si ti owo dinaru ogorun nbe ninu re, mo si mu lo si odo Ojise Olohun -ki ike ati ola Olohun ma ba-, O ba sope (ojise Olohun): se ifiwelo re fun odun kan. Mo ba se ifiwelo re sugbon n ko ri eniti o nii. Mo ba losi odo re (odo ojise Olohun), o si sope: so kerengbe re ati okun re, ti eniti o nii ba wa ki o fun, sugbon ti ko ba wa se anfaani pelu re" Bukhari.

6.    Idabobo fun ebi:
Islam se akotan amojuto molebi pelu opolopo akolekan ati amojuto nitoripe oun ni ona kan soso ti Olohun se fun ima be gbere omoniyan nibi idipo ara eni (khalifah) lori ile. O wa se iwa ibaje pelu re, tabi oun ti o le je okunfa jija re, abi ti o le je okunfa adinku ati eyi ti o le ko ale baa laini idi pataki ti sharia gba wole, ni oun ti o je eewo ninu sharia. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
"وَإِذَا تَوَلَّى سَعَى فِي الْأَرْضِ لِيُفْسِدَ فِيهَا وَيُهْلِكَ الْحَرْثَ وَالنَّسْلَ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ الْفَسَادَ"
Itumo: " Nigbati o ba pa eyinda, yoo gbero lati se ibaje lori ile ati lati pa awon oun ogbin ati awon nkan osin run; Olohun ko nife si ibaje" Suratu Bakorah: 205.
Islam se oyun sise ni eewo toripe o je ise ibaje lori emi omoniyan ayafi nigbati o ba je ewu lori isemi iya.
Nipaapa Sharia se awon musulumi loju oyin sise iyawo nitori ki won le ma bi opolopo omo. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: E ma fe ololufe olubimo, dajudaju emi yoo fiyin po ni ijo lori awon ijo yoku ni ojo igbende" Ahmad, Abu Dawood, An-Nasai, ati Ibn Hibaan ni won gba wa. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: Eyin odo lokunrin! Eniti o ba ni ikapa (ikapa ibalopo ati inawo fun iyawo) ki o lo se igbeyawo, dajudaju o je okunfa fun rire oju sile ati siso abe (kuro nibi sina), eniti ko ba ni ikapa (lati se iyawo) ki o ya maa gba awe toripe o je gaga kuro nibi nkan omo-okunrin ".

7.    Idabobo fun Molebi:
Okun ebi je oun pataki ninu Islam, toripe o je ipile fun akojo awujo, ati nitori ati se idabobo fun un kuro nibi darudapo ni Islam fi se akolekan ti o pe fun un. Nigbati o je pe ebi ni gaga eleyi ti yoo ma so omoniyan po ma ara won, ti alasunmo yoo mo alasunma re ti yoo si ma pe eto re ti Olohun se ni oranyan fun nibi siso okun ebi po ati pipe eto. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe: E mo ebi yin eleyi ti o pandandan ki e so, dajudaju siso okun ebi po je okunfa ife ninu ebi, pipo owo, ati alekun ojo ori." Ahmad ati Tirmidhi logba wa.
Nitori eleyi ni Islam fi ni akolekan nla lori siso o kuro nibi adapo eleyi ti o le fa fifonka awujo ati fife iyawo ni ona ti ko leto ati jije ninu ogun eniti ko leto si ogun ati ki didena eniti o ni eto si ogun kuro nibi eto re.
Nipaapa Islam ri awon ti o siwaju re lodo awon larubawa tabi awon ijo miran ninu ofin ti o gbajumo lodo won ti o si sopo mo kiko ebi jo si oun ti ko dara. Ninu awon ofin ti Islam ri si ibaje ni:
* Ofin At-Tibni: Eleyi ni siso omo olomo d'omo tabi pipee pelu oruko ti kii se ti baba re, ti yoo wa ma be fun ninu eto ati ohun ti o je dandan gegebi o se nbe fun awon omo bibi inu re. Olohun so bayi pe:
" مَا جَعَلَ اللَّهُ لِرَجُلٍ مِنْ قَلْبَيْنِ فِي جَوْفِهِ وَمَا جَعَلَ أَزْوَاجَكُمُ اللَّائِي تُظَاهِرُونَ مِنْهُنَّ أُمَّهَاتِكُمْ وَمَا جَعَلَ أَدْعِيَاءَكُمْ أَبْنَاءَكُمْ ذَلِكُمْ قَوْلُكُمْ بِأَفْوَاهِكُمْ وَاللَّهُ يَقُولُ الْحَقَّ وَهُوَ يَهْدِي السَّبِيلَ * ادْعُوهُمْ لِآبَائِهِمْ هُوَ أَقْسَطُ عِنْدَ اللَّهِ فَإِنْ لَمْ تَعْلَمُوا آبَاءَهُمْ فَإِخْوَانُكُمْ فِي الدِّينِ …"
Itumo: " Olohun ko fun eniyan kan ni okan meji ninu ara re, Olohun ko si se awon iyawo yin ti e nfi won we iya yin, Kosi se (Olohun) awon omo ti e npe mo ara yin ni omo bibi inu yin, oro enu yin lasan ni iwonyi. Ododo ni Olohun nso, Oun ni o si ma nfi ni mona. * E ma fi awon oruko baba won pe won, eleyi ni o se dede ju ni odo Olohun, ti e ko ba mo awon baba won e ma pe won ni omo-iya ninu esin.." Suratu Ahzaab: 4-5.
* Ofin ise ifirinle omo: Eleyi ni ki won se alaifi omo ti o ba ilana sharia mu ti si baba re titi yoo fi se afirinle re, nigbagba ti yoo si yonu si fifi ti re si molebi re. Islam se eleyi ni eewo nitori iyepere ti o nbe nibe fun itakoko igbeyawo ati nitori gbigbe alamori molebi fun ife-inu oko, ati nitori iyepere aponle ti nbe nibe fun obinrin nibi iyi re, ati nitori ise opinya larin awon omo ati ebi ti nbe nibe. Bayi ni Islam se afirinle pe eyikeyi omo won ko gbodo se afiti re si odo okunrin ayafi pelu iba obinrin lopo ni ibamu si ilana sharia. Pelu titakoko yigi ni ilana sharia ni won yoo maa se afiti omo si odo okunrin laini bukata si fifi owo si re ki won to se afiti re si lodo, abi sise afirinle re nigbangba, nitori oro Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- to so bayi pe: " sise afiti omo si odo okunrin wa lori biba iyawo lopo (pelu ilana sharia)". Ayafi ti o ba rinle pe iyawo re se ijamba re ti o si loyun fun okunrin miran. Awon eleyi ni idajo ti o romo ninu esin Islam, ti alaye lori re wa lakosile.
Ofin Khului': Eleyi ni yiyonda fun olori-ile lati ko awon ara ile re ti o rinle pelu sharia afiti won si i, ti okun ebi re pelu won ati okun ebi won pelu re yoo wa di gige, ti yoo wa di ajoji si won. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe: "Nkan meji ti o je iwa keferi (aigba Olohun gbo) nbe lara omo-enia * bibu enu ate lu ebi, * ati ima sun rara le oku." Muslim logba wa.
Sise afiti Obirin si odo oko re leyin igbe-iyawo:
Sharia Islam se amojuto iwo obinrin nibi oruko re, oruko ebi re, ati idile re leyin igbeyawo. Sise afiti re si oruko oko re ati si oruko molebi ati idile oko re je eewo. Eleyi je aponle fun obinrin laisi iyemeji nibe. Aponle wo ni oto eleyi, sise afirinle pelu ola obinrin, ati didaduro re ati ise dede re pelu okunrin nibi iyi omoniyan wo loto eleyi. Ojise Olohu-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe:" Eniti o ba fi ara re ti si odo eniti kii se baba re abi ti o mu elomiran ni olowo re, ki igbejina si ike Olohun ki o ma a ba, ati ti awon Malaika, ati ti awon enia lapapo." Sahih Ibn Maajah.

Idabobo fun awon eto ole ninu omo enia:
Ninu re:
1. Idabobo fun eto ole ati alaini ikapa: Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: Olohun ko ni fo ijo kan mo (kuro ninu ese) eyiti ole koni ri eto re gba lowo alagbara lai jepe yoo ma beru (lai jepe yoo ri inira). O wa ninu sahih Al-Baehaqi, Ibn Maajah, ati Al-Haakim.
2. Idabobo fun awon eto onibukata: Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" وَآتِ ذَا الْقُرْبَى حَقَّهُ وَالْمِسْكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ وَلَا تُبَذِّرْ تَبْذِيرًا * إِنَّ الْمُبَذِّرِينَ كَانُوا إِخْوَانَ الشَّيَاطِينِ وَكَانَ الشَّيْطَانُ لِرَبِّهِ كَفُورًا "
Itumo: " Ati ki o ma fun awon alasunmo re ni eto won ati awon alaini, ati omo ori irin, ki o si ma se ma na inakuna* Dajudaju awon oni inakuna je omo iya esu, be si ni esu je eniti o ko tiikun si Oluwa re." Suratu Israi': 26-27. Olohun tun so bayi pe:
" وَأَمَّا السَّائِلَ فَلَا تَنْهَرْ "
Itumo: " Atipe ki o mase kanra mo alagbe" Suratu Duha:10.
3. Idabobo fun awon eto omode: Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: " Eniti ko ba ma pon omo de wa le, ti ko si eto agba kii se ara wa." Sahih Bukhari ati Abu Dawood.
4. Idabobo awon eto agbalagba: Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: "Ninu gbigbe Olohun tobi ni sise aponle fun musulumi ti oni ewu lori (eniti o dagba titi o fi ni ewu lori), ati eniti o ha kur'ani ti kii se olukoja ala nibe (ti kii se olukoja ala ni ilekoko ati ise), ti kii se oluse aseeto pelu e, ati sise aponle olori ti o je oni-dede." Sahih- Abu Dawood logba wa.
5. Idabobo fun awon alaisan: Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe:" Eto musulumi si musulumi marun ni; didahun salamo, bibe alaisan wo, titele oku (losi ite), jije ipe, ati sise adua fun eniti o ba sin.'
6. Idabobo fun eto awon omo-orukan: Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" فَأَمَّا الْيَتِيمَ فَلَا تَقْهَرْ "
 Itumo:" Nitorina ma se ni omo orukan lara." Olohun tun so bayi pe:
" إِنَّ الَّذِينَ يَأْكُلُونَ أَمْوَالَ الْيَتَامَى ظُلْمًا إِنَّمَا يَأْكُلُونَ فِي بُطُونِهِمْ نَارًا وَسَيَصْلَوْنَ سَعِيرًا "
Itumo: " Dajudaju awon eniti won je nkan-ini omo-orukan ni ti abosi, dajudaju ina ni won nje si inu ikun won, won yoo si wo ina elejo fofo." Suratu Nisai':10.
7. Idabobo fun awon eto awon omo: Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" وَلَا تَقْتُلُوا أَوْلَادَكُمْ مِنْ إِمْلَاقٍ نَحْنُ نَرْزُقُكُمْ وَإِيَّاهُمْ "
Itumo: "… E si mase pa awon omo yin nitori iberu osi…" Suratu An'am: 155.

Idabobo awon alumoni ti o je ti Isenbaye (ojuda) ati jijina si ifowo abuku kan an
Dajudaju gbogbo ohun ti nbe ni ori-ile ninu awon alumoni ki i se oun-ini fun enikan, tabi fun ijo kan bi ki i sepe won je oun ajoni fun awujo lati le se anfani ni ara re pelu oun ti yoo mu dada wa fun omoniyan kookan ati awujo. Ninu iwo gbogbo eniyan ni awujo Islam oun ki won dina mo eniti o ba fe se ibaje pelu awon alumoni yii, tabi o fe lo si bi oun ti ko ba erongba ilana sharia mu. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" اللَّهُ الَّذِي سَخَّرَ لَكُمُ الْبَحْرَ لِتَجْرِيَ الْفُلْكُ فِيهِ بِأَمْرِهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ * وَسَخَّرَ لَكُمْ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مِنْهُ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ "
Itumo: " Olohun ni Eniti o te okun lori ba fun yin ki awon oko oju-omi le ma rin ninu re pelu ase Re ati ki e le ma wa ore-ajulo Re ati ki e le ma dupe* Atipe O te lori ba fun yin oun ti o wa ni sanma ati oun ti o wa ni ile patapata lati odo ara Re, Dajudaju awon ami nbe ninu eleyi fun awon eniyan ti n ronu." Suratu Jathiya:12-13.

Awon Eto Ajoni ati Adani ninu Islam
Pelu pe Islam nsare lati so okun ajosepo laarin awon ara awujo re, yala okun alasunmo eleyi ti won npe ni (okun-ebi) ninu Islam ti Olohun pase siso re, ti O si se ileri iya nla fun eniti o ba ge. Olohun ti ola RE ga julo so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَاءً وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي تَسَاءَلُونَ بِهِ وَالْأَرْحَامَ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا "
Itumo: Eyin omoniyan! E beru Oluwa yin, Eniti O se eda yin lati ara emi kansoso, O si se eda iyawo re lati ara re, O si tan opolopo okunrin ati obirin kale lati ara awon mejeji, e beru Olohun Eniti e fi nbe ara yin ati okun ibi, dajudaju Olohun je Oluso lori yin" Suratu Nisai:4.
Tabi ajose awon eniti won jina, eleyi ti nso okun ajose larin awon ara awujo pelu ara won lati le fa ajosepo ati irepo laarin awujo Islam. Won pa musulumi ni ase ki o pe awon oranyan ati eto ti n be lori re si omo iya-re musulumi. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: e mo maa se keta ara yin, e mo maa yin eniyan ju nitori ki elomiran mo gba itanje pelu re, e mo maa binu si ara yin, e mo maa yan ara yin lodi, ki apakan yin ma si maa ta oja apakeji, e je erusin Olohun, musulumi omo-iya musulumi ni o je, ko gbodo se abosi re, ko gbodo yepere re, ko gbodo yonda re (fun ota), ipaya Olohun nibi ni o wa, o si (ojise Olohun) na ika si igbaya re ni emeta, otito fun omoniyan ni aburu ki o yepere omo-iya re musulumi, Musulumi kan si Musulumi ewo ni, eje re, dukia re ati omoluabi re. Muslim ni ogba wa.
Islam tun se ni oranyan awon eto adani ati eto ajoni. Awon eto adani ninu Islam ni 23:
* Awon eto Olohun eleyi ti nbe ninu gbolohun ijeje (La illaha illa Lahu)" Ijeje yi ntoka si:
a. Ise Olohun lokan nibi ije Oluwa, eleyi ti nse ifirinle bibe Olohun, atipe Oun nikan ni Oluda agbanla-aye pelu gbogbo oun to nbe ninu re, atipe Oun nikan ni Oluni aye Oludari gbogbo oun ti nbe ninu re. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ "
Itumo: Eteti ki egbo, ti Re ni siseda ati ase. Ibukun ni fun Olohun, Oluwa gbogbo eda." Suratu A'raf: 54.
b. Ise Olohun lokan nibi oruko Re ati iroyin Re, eleyi ti se adisokan pe Olohun ti ola Re ga julo ni awon oruko ti won rewa julo ati awon iroyin ti won ga, atipe O mo kanga kuro ni alebu ati adinku. Olohun so bayi pe:
" وَلِلَّهِ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَى فَادْعُوهُ بِهَا وَذَرُوا الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي أَسْمَائِهِ سَيُجْزَوْنَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ "
Itumo:" Ti Olohun ni awon oruko ti o dara julo, nitorina e ma fi won pe E ki e si fi sile awon eniti won gunri kuro nibi oun ti awon oruko Re ntoka si, Won yio san won lesan ohun ti won se nise." Suratu A'raf: 180.
A o fi rinle fun Un oun ti O se afirinle re fun ara Re ninu iwe Re (Al-Qur'an), tabi ti ojise Re (ki ike ati ola Re ma a ba- fi rinle fun Un, eleyi ti ko si afijo fun Un rara ninu awon eda, lai si ofintoto (itopinpin) nipa Re,, abi ikotiikun si , abi ise ifiwe Re, abi ise afijo Re. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" لَيْسَ كَمِثْلِهِ شَيْءٌ وَهُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ"
Itumo:" Kosi kinikan ti o dabi Re, (Olohun) Oun ni Olugboro Oluriran." Suratu Shura: 11.
c. Ise Olohun lokan nibi ijosin fun Un, eleyi ni adisokan paapa pe Olohun ni Oluwa ododo, kosi Olohun miran niti ododo leyin Re, kosi Olu-josin fun miran ti o leto ati gbe ijosin kan ninu awon ijosin fun Un leyin Re. Olohun so bayi pe:
" وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ مِنْ رَسُولٍ إِلَّا نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدُونِ"
Itumo: " Atipe Awa ko ran ojise kan nise siwaju re ayafi ki A ranse si i pe dajudaju ko si olohun miran ayafi Emi, nitorina ki e ma sin Mi."
Bakanna ki gbogbo ise olujosin ati oro re ba ofin Olohun mu ti yoo si maa gbero pelu re Oju-Olohun (yoo ma se afomo re fun Olohun). Olohun so bayi pe:
" إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ "
Itumo:"…Dajudaju awon eniti won nse igberaga kuro nibi ijosin mi I laipe won yoo wo Ina jahanama ni eni iyepere." Suratu Ghafir: 60.
Eleyi nipe ki eru ko gbe duro ohun ti Olohun se ni oranyan le lori gegebi irun kiki eleyi ti o sepe ninu eso re ninu Islam ni iko-ara ro kuro nibi iwa alufansa (iwa ibaje) ati iwa ti okan ko. Olohun so bayi pe:
" إِنَّ الصَّلَاةَ تَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ "
Itumon: Dajudaju irun kiki ma nko iwa ibaje ati iwa ti okan ko…) Suratu Ankaabut: 45.
Ati Zakat eleyi to sepe ninu eso re ni fifo okan mo ati mimo re kuro nibi aburu ahun. Olohun so bayi pe:
" خُذْ مِنْ أَمْوَالِهِمْ صَدَقَةً تُطَهِّرُهُمْ وَتُزَكِّيهِمْ بِهَا"
Itumo: " Gba itore (Zakah) ninu oro won ki o fo won mo, ki o si so won di mimo pelu re.."
Ati awe eleyi ti o sepe ninu anfani re ni iberu Olohun ati kiko fun emi kuro nibi oju kokoro re. Olohun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ "
Itumo: " Eyin ti egbagbo! Won se awe ni oranyan leyin lori gegebi won ti se ni oranyan le awon ti o siwaju yin lori, ki e le beru Olohun.' Bakorah:183.
Ati Hajji eleyi to sepe ninu anfani re ni oro ti Olohun so bayi pe:
" لِيَشْهَدُوا مَنَافِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُوا اسْمَ اللَّهِ فِي أَيَّامٍ مَعْلُومَاتٍ عَلَى مَا رَزَقَهُمْ مِنْ بَهِيمَةِ الْأَنْعَامِ فَكُلُوا مِنْهَا وَأَطْعِمُوا الْبَائِسَ الْفَقِيرَ"
Itumo: "Ki won le ri anfani ti o wa fun won, ati ki won le ma ranti oruko Olohun ninu awon ojo ti o je mimo lori awon nkan ti O pa lese fun won ninu eran osin, nitorina e je ninu won ki e si fun awon eniti ara nni ti won je talika." Suratu Haj:28.
Atipe dajudaju gbogbo ijosin ninu Islam se dede pelu agbara omoniyan eleyi ti o sepe won ko la bo lorun ju ohun ti o ni ipakani re lo, nitoripe (Islam) o je esin irorun. Olohun so bayi pe;
" يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ "
Itumo: ".. (Olohun) O nfe fun yin Irorun, kosi fe fun yin inira.." Bakorah:185.
Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe:" …Ti mo ba pa yin lase nkankan e se bi e se ni ikapa ni.." Bukhari ati Muslim.
Sugbon awon ase yii ati awon ijosin yii leje afoju fo ni gba miran ni apejuwe;
* Irun kiki ninu oranyan re ni diduro nigbati agbara bawa sugbon ti ko bani agabara lati ki ni iduro yoo kii ni ijoko, ti ko ba ni agbara lati ki ni ijoko yoo ki pelu fifi egbe le-ile, ti ko ba ni agbara lati se eleyi yoo kii pelu sise itoka. Bakanna ninu oranyan re ni kiki ni apapo (jamaah) pelu awon olukirun ni masalasi fun okunrin ti oranyan yii yoo si di agbekale (ti koni je oranyan) ni asiko aisan, iberu, otutu tabi ojo nla. Bakanna ni gbigbe oranyan kiki irun sile fun obirin ti nse eje osu ati ibimo lowo titi yoo fi mora lai ni san awon irun naa pada.
*kikuro ni oranyan zakat fun eniti ko ni odiwon owo ti saka wo, iru eniyan bayi won yoo tun fun ninu owo zakah ti o ba je alaini onibukata.
*kikuro ni oranyan awe fun alaisan ti ko si ireti Alafia fun, yoo se itanran, sugbon eni ti ireti alafia ba nbe fun yoo san gbese re pada nigbati o ba ni Alafia, bakanna ni agbalagba ti awe le fun lati gba. Bee naa ni oloyun nigbati o ba nberu lori ara re abi oyun re, yoo san gbese re pada leyin ti o ba bimo tan. Be naa si iyonda jijeun fun arinrin-ajo toripe irin-ajo okunfa kan ni ninu awon okunfa ile-koko, yoo san awon awe ti o ja pada, bakanna ni obinrin ti nse eje osu ati ibimo lowo ko ni gba awe titi yoo fi se imora, sugbon yoo gba awon ojo ti o ja pada.
* Kikuro ni oranyan hajj fun eni ti ko ni agbara owo ati ti ara. Sugbon eniti koba ni agbara ti ara ti o ba ni agbara owo yoo ran eniti yoo se hajj fun un, sugbon eniti ko ni agbara owo, hajj kii se oranyan le lori titi yoo fi ni owo ti yoo ju bukata re ati ti awon ara-ile re lo nitori oro Olohun ti ola Re ga julo bayi pe:
" وَلِلَّهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ الْبَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلًا"
Itumo:" …Olohun se irin-ajo lo si ile na (kabah) ni oranyan fun gbogbo enikeni ti o ba ni agbara.." Suratu Aal-Imran:97.
* Ti eniyan ba nberu iparun lori ara re, o leto fun lati je abi mu ninu oun ti Olohun se ni eewo ninu eran okunbete, abi eje, abi eran elede, ati oti mimu ni odiwon oun ti yoo fi mu emi re duro, ko leto fun lati je ajeyo. Olohun so bayi pe:
" فَمَنِ اضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ"
Itumo:" …Eniti inira ba mu (jee) ti ki i se ti ife inu, ati ire koja enu ala kosi ese fun…" Suratu Bakorah:173.
Sayid Kutub ki Olohun yonu si so bayi nibi alaye lori ese oro yi pe: eleyi ni adisokan eyiti o se afirinle omoniyan ni omoniyan, ki i se eranko, ki i se malaika, bee si ni ki i se esu, o se afirinle re gegebi o se ri pelu gbogbo oun ti nbe ni ara re ni ale ati agbara, o si mu gegebi eda ti o ko jo lati ara oun ti o yato si ara won, ati lakaye ti o dara, ati emi ti o dara, o si labo lorun awon ise oranyan eleyi ti o ni ikapa lori re, o si se akiyesi ise deedee laarin ilabolorun (ise oranyan) ati ikapani laisi ifunpinpin ati inira.
Awon Eto Ojise Muhammad- ki ike ati ola Olohun ma a ba- eleyi ti nbe ninu gbolohun ijeje (Shahadah) pe dajudaju ojise Olohun ni. Ijeje yi ntoka lori:
a. Titele ase re nibi oun ti o ba pa lase: Olohun so bayi pe:
" مَنْ يُطِعِ الرَّسُولَ فَقَدْ أَطَاعَ اللَّهَ وَمَنْ تَوَلَّى فَمَا أَرْسَلْنَاكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا "
Itumo: Enikeni ti o ba tele ti Ojise na, lotito o ti tele ti Olohun, enikeni ti o ba pehinda, Awa ko ran o pe ki o je oluso le won lori." Suratu Nisai:80.
b. Gbigba ni olododo ninu ohun ti o ba so, Olohun so bayi pe:
" وَمَا يَنْطِقُ عَنِ الْهَوَى * إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْيٌ يُوحَى"
Itumo:" Atipe ki soro pelu ife-inu* Oun Ko je kinikan bikose ise ti A ran (si i)." Suratu Najm: 3-4.
c. Ijina ati igbejusile ohun ti o ba se ni eewo; Olohun so bayi pe:
" وَمَا آتَاكُمُ الرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَاكُمْ عَنْهُ فَانْتَهُوا"
Itumo:" …Ohunkohun ti Ojise na ba fun yin ki e gba a, ohunkohun ti o ba si ko fun yin ki e ko o…" Suratu Hashr: 7.
d. A ko gbodo sin Olohun ayafi pelu oun ti o ba se ni ofin; Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- so bayi pe: Enikeni ti o ba se ise kan ti ko si ase wa lori re, A o da ise na pada fun." Muslim:1718.
Eto awon Annabi ati awon Ojise lapapo:
Ninu ofin Islam, musulumi kan ko le je musulumi titi yoo fi ni igbagbo pelu gbogbo awon ojise ati awon Annabi Olohun, yoo si ni ife won, yoo si maa pon won le bere latori Adam-ki ike Olohun ma a ba- titi de ori Annabi Muhammad-ki ike ati ola Olohun ma a ba-. Eni ti ko ba ni igbagbo si okan ninu won yoo di keferi (alaigbagbo), yoo si jade kuro ninu Islam. Olohun so bayi pe:
" إِنَّ الَّذِينَ يَكْفُرُونَ بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ وَيُرِيدُونَ أَنْ يُفَرِّقُوا بَيْنَ اللَّهِ وَرُسُلِهِ وَيَقُولُونَ نُؤْمِنُ بِبَعْضٍ وَنَكْفُرُ بِبَعْضٍ وَيُرِيدُونَ أَنْ يَتَّخِذُوا بَيْنَ ذَلِكَ سَبِيلًا* أُولَئِكَ هُمُ الْكَافِرُونَ حَقًّا وَأَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا مُهِينًا"
Itumo: "Dajudaju awon ti ko gba Olohun gbo ati awon ojise Re ti won si ngbero lati se opinya larin Olohun ati awon ojise Re, ti won si nwipe: Awa gba apakan gbo (ninu awon ojise) awa ko si gba apakan gbo, won si nfe lati mu oju ona kan larin (mejeji) yi. * Awon wonyi ni alaigbagbo ni ododo, A si ti pese iya elete-ero fun awon alaigbagbo." Suratu Nisai: 150-151.
Ojise Muhammad-ki ike ati ola Olohun ma a ba- je opin awon Annabi ati awon ojise, ofin re (Sharia) je oun ti o wa lati pe awon ofin sama ti o siwaju re, ati lati pa'are nitoripe awon ojise ti o siwaju re wa fun asiko kan pato fun awon ijo kan pato, yato si ojise Islam (Muhammad) eniti won ran si gbogbo eniyan lapapo titi di ojo igbende. Olohun so bayi pe:
" وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا كَافَّةً لِلنَّاسِ بَشِيرًا وَنَذِيرًا وَلَكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ "
Itumo:" Atipe Awa ko ran o nise ayafi si gbogbo eniyan ni olufunni niro idunnu ati olukilo, sugbon opolopo eniyan ko mo." Suratu Saba": 28.
Nitorina Musulumi je eniti won fe pe ki o tan iranse Islam ka ati ofin re fun awon elomiran ninu awon ti o siwaju re. Eleyi ni oun ti Islam npepe si, eniti ko ba gba, awijare ti wa le lori. Olohun so bayi pe:
" لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ "
Itumo:"…Kosi ifi agbara mu ni ninu esin, nipaapaa ona otito ti farahan kuro ninu ona isina…" Suratu Bakora:256.
Eto awon Obi mejeji
Eto yi nbe nibi itele ase won nigbakugba ti won ko ba ti pa ase ti o yapa ase Olohun, ati imo maa yapa ase won, ati tite ase won, ati imo se daadaa si won, ati imo na fun won, ati imo pese ohun ti won ni bukata si fun won ninu onje, ati mimu, ati wiwo, ati ibugbe, ati iyepere ara eni fun won, ati imo moo se motomoto le won lori, ati sise suuru lori ise amojuto won, ati imo se akiyesi oun ti won nfe (imolara), imo moo so oro ti o le ko inira ba won, ti o si le ko ipalara ba imolara won nitoripe Olohun ti ola Re ga julo- so eto Re mo eto won. Olohun so bayi pe:
" وَقَضَى رَبُّكَ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا إِيَّاهُ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا إِمَّا يَبْلُغَنَّ عِنْدَكَ الْكِبَرَ أَحَدُهُمَا أَوْ كِلَاهُمَا فَلَا تَقُلْ لَهُمَا أُفٍّ وَلَا تَنْهَرْهُمَا وَقُلْ لَهُمَا قَوْلًا كَرِيمًا* وَاخْفِضْ لَهُمَا جَنَاحَ الذُّلِّ مِنَ الرَّحْمَةِ وَقُلْ رَبِّ ارْحَمْهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيرًا "
Itumo:" Atipe Oluwa Re palase pe: E ko gbodo sin kinikan ayafi Oun nikan, ati ki e ma se rere si awon obi mejeji. Bi okan ninu won ba dagba si o lowo abi awon mejeji, o ko gbodo se sio won, bee si ni o ko gbodo jagbe mo won, sugbon ki o ma ba won soro aponle*    Ati ki o re ara nile fun won niti anu ati ki o ma sope: Oluwa, ba mi ke awon mejeji gegebi won ti ke mi ni kekere." Suratu Israi":23-24. Ati nitori oro ojise Olohun-ki ike ati ola Re ma a ba- to so bayi pe:" Iyonu Olohun nbe nibi iyonu obi, ibinu Olohun nbe nibi ibinu obi." Tirmidhi ati Ibn Hiban ni won gba wa.
Awon eto yi je oranyan fun awon obi mejeji koda ko sepe esin won yapa si esin ti e, niwonba igba ti won ko ba ti pase oun ti o je ewo ninu sharia, nitori Hadith Asma' omo Abi Bakr-ki Olohun yonu si awon mejeji- to sope: Iya mi wa be mi wo ti o si je osebo ni asiko ti awon kuraeshi se adeun pelu Ojise Olohun- ki ike ati ola Re ma a ba- mo wa bi ojise Olohun- ki ike Olohun ma a ba- le re, mo sope: Ire ojise Olohun: Iya mi wa be mi wo ni eniti nfe ki nse dada si i, se ki nda iya po? O (ojise Olohun) sope: beni, da iya re po." Bukhari ati Muslim.
Iya saju baba nibi sise dada si won, ati nibi siso ebi won po, ati nibi sise pelepele pelu won, ati nibi inife rere fun won, nitori Hadith baba Huraerah- ki Olohunyonu si- pe: arakunrin kan wa ba Annabi-ki ike Olohun ma a ba- o wa sope: Ire Ojise Olohun! Tani o leto si sise dada si mi julo? O (ojise Olohun) sope: iya re, leyinna iya re, leyinna iya re, leyinna baba re, leyinna alasunmo re julo ninu awon molebi. Bukhari ati Muslim.
O se adayanri iya pelu eto meta, o si se adayanri baba pelu eto kan, eleyi kori be ayafi bikosepe nitori pe iya gbe opolopo ilekoko ati inira ti baba ko gbe, gegebi Olohun se so nipa re pelu oro Re:
" حَمَلَتْهُ أُمُّهُ كُرْهًا وَوَضَعَتْهُ كُرْهًا "
Itumo:"…Iya gbe oyun re pelu inira, o si bi i pelu inira.." Suratu Ahkof:15.
Eto Oko lori Iyawo re*
* Opomulero ni Oko je, won yoo bi okunrin nipa awon ara-ile re, yoo si mo se ohun ti o ri wipe yoo je anfani fun molebi. Olohun so bayi pe:
الرِّجَالُ قَوَّامُونَ عَلَى النِّسَاءِ بِمَا فَضَّلَ اللَّهُ بَعْضَهُمْ عَلَى بَعْضٍ وَبِمَا أَنْفَقُوا مِنْ أَمْوَالِهِمْ "
 Itumo: " Awon okunrin ni opomulero fun awon obinrin nitoripe Olohun se ajulo fun apakan won ju apakan lo, ati nitori ohun ti won na ninu dukia won.." Suratu Nisaii:34.
 Eleyi nitori pe awon okunrin ni opolopo igba won yoo ma ba igba lo pelu lakaye won, yato si awon obinrin ti o sepe igbarata ni iroyin to poju fun won lori awon isesi won, eleyi ko tumo sipe ki o mo moo fi oro lo o, ati ise imulo irori re nibi awon alamori ti o je adayanri fun isemi aye loko-laya.
* Titele ase re nigbati ko ba ti pase oun ti o je iyapa Olohun. Lati odo Zayd omo Arqom-ki Olohun yonu si i- ti o so bayi pe: Ojise Olohun- ki ike Olohun ma a ba- so bayi pe: obinrin ko le pee iwo Olohun lori re titi ti yoo fi pe iwo oko re tan." Tabarani ni o gba wa pelu egbawa ti o ni alafia.
* Kogbodo maa la bo lorun oun ti ko lagbara re, ko si gbodo maa bere lowo re oun ti ko si ni ikapa re.
* Ki o moo so dukia re ati awon omo re, ati ije omoluabi re. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma a ba- so pe:' eyi ti o dara julo ninu awon obinrin ni eyi ti o sepe ti o ba wo yoo dun o ninu, ti yoo si moo tele ase ti o ba pa, ti yoo si mooo so eyin re nibi ara re ati owo re." Tabarani ni o gba wa ninu tira ti nje " Sahihu Al-Jami':3299.
* Ko gbodo jade kuro ninu ile re ayafi pelu iyonu ati imo si re, kosi gbodo mu wo inu ile re eniti o ko rira re. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma a ba- so bayi pe: " Dajudaju e ni eto lodo awon iyawo yin, awon iyawo yin na si ni eto lodo lori yin. Awon eto tiyin lori awon iyawo yin nipe won ko gbodo mu wo ibusun yin eniti e korira, won ko gbodo yonda wiwo inu-ile yin fun eniti e korira re, eteti-e gbo, eto won (awon obinrin) lori yin ni ki e ma se rere si won nibi aso wiwo won ati nibi ounje jije won." Tirmidhi ati Ibn majah ni won gba wa.
"Gbolohun won ko gbodo mu wo ibusun yin" Imam Al-Khatabi sope itumo re nipe: won ko gbodo yonda fun enikeni ninu awon okunrin lati wole ki o wa ma ba won soro. Si s'oro awon okunrin pelu awon obinrin ninu isesi awon larubawa, won ko ri si alebu. Nigbati aya iboju (eha sise) sokale ti awon obinrin wa ni adinku, won se ni eewo imo ba won soro ati imo joko pelu won.
* Eto Iyawo lori oko re
a. Owo-ori; eleyi ti o je eto ti o kanpa fun iyawo lori oko re. Olohun so bayi pe:
" وَآتُوا النِّسَاءَ صَدُقَاتِهِنَّ نِحْلَةً فَإِنْ طِبْنَ لَكُمْ عَنْ شَيْءٍ مِنْهُ نَفْسًا فَكُلُوهُ هَنِيئًا مَرِيئًا "
Itumo:" E fun awon obirin ni owo-ori won ni tokan tokan, sugbon bi won ba fi inudidun yonda nkankan ninu re fun yin funra won, nigbana e je e pelu irorun ati adun." Suratu Nisai:4.
b. Deedee ati dogbandogba fun eniti o ba ni iyawo meji abi jube lo. O di dandan fun un deedee laarin won nibi ounje, aso wiwo, mimu, ibugbe, ati nibi orun sisun nitori oro Ojise Olohun-ki ike Olohun ma a ba- to sope:" Eniti o ba ni iyawo meji ni o ba gbe ola fun kan ninu won, yoo wa ni ojo igbende ni eniti egbe re ye e." Abu Dawood, An-Nasai, At-tirmidhi, Ad-darimi, ati Ibn majah ni won gba wa.
c. Nina owo fun un ati fun awon omo re, ati mimo fun ni owo ti o ni bukata si ni ibamu si agbara ati ikapa ni oko re. Olohun so bayi pe:
" لِيُنْفِقْ ذُو سَعَةٍ مِنْ سَعَتِهِ وَمَنْ قُدِرَ عَلَيْهِ رِزْقُهُ فَلْيُنْفِقْ مِمَّا آتَاهُ اللَّهُ لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا مَا آتَاهَا"
Itumo:" Eniti o ni oro pupo ki o na ninu pupo re, eniti won si diwon arisiki re fun ki o na ninu ohun ti Olohun pese re fun, Olohun ko la bo emi kan lorun koja ohun ti o fun u…" Suratu Talaq: 7.
Islam nse awon musulumi ni oju oyin lori eleyi, o se inawo yi ni okan ninu awon sadaka (sara) ti won yoo san won lesan lori re nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma a ba- fun Sa'd omo Abi Waqos:" O ko ni na owo kan ti o fi nwa oju-rere Olohun ayafi ki Olohun O san o ni esan pelu re, koda to fi mo isu-okele ti o fi si enu iyawo re…" Bukhari ati Muslim.
Obinrin ni eto ki o mu ninu owo oko re pelu ai mo si re ti o ba je ahun ti ko fun un ni oun ti yoo to ati awon omo re, nitori Hadith Hind omo Utbah ti o sope: Ire ojise Olohun! Dajudaju baba Sufyan je ahun, ki i fun mi ati omo mi ni oun ti yoo to wa ayafi pelu ki nmu ninu owo re ti ko si ni mo si. Ojise Olohun sope: Mu oun ti yoo to o ati omo re pelu dede." Bukhari.
d. Orun sisun ati ibalopo loko-laya: eleyi je okan ninu awon eto ti o se koko eleyi ti ofin-Islam (sharia) pa oko lase pipe re ati nini akolekan pelu re. Obinrin gegebi iyawo ni bukata si oko ti yoo maa se pelepele pelu re, ati oko ti yoo maa ba sere, ti yoo si maa yo nibi adamo re, ti ko fi ni ni inira lo si ibi awon alamori ti igbeyin re ko dara, nitori oro Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma a ba- fun Jaabir-ki Olohun yonu si- pe: Ire Jaabir! Nje o se Iyawo bi? Mo sope: be ni. O (Ojise Olohun) sope: Nje omoge ni abi adelebo? Mo sope: adelebo. O sope: o ba fe omoge ti o mo ba a sere ti oun naa yoo si mo ba o sere, abi ti o maa pa a lerin ti oun naa yoo si moo pa o lerin. Bukhari: 6024.
e. Imaa se idabobo ikoko re ati imaa moo so aleebu re sita ati imaa se ifipamo oun ti o ba ri abi ti o ba gbo lodo re, ati imaa se ifipamo oun ti o ba waye laarin won nibi ajosepo aladayanri. Nitori oro Ojise Olohun-ki ike Olohun ma a ba- ti o sope:"dajudaju eniti o je alaburu julo ni eniyan ni odo Olohun ni ojo igbende ni okunrin ti o se asepo pelu iyawo re ti iyawo re na si sun mo ti o (okunrin) wa nfon ikoko (iyawo) re ka (ti o wa fon oun ti o sele larin won ka lodo awon ore re)."Muslim lo gba wa.
f. Imaa ba lopo ni ilopo ti o dara, ati imaa ba se asepo pelu rere, ati imaa se ijiroro pelu re nibi awon alamori ti o nise pelu loko-laya, (oko) kogbo mo se nkan pelu ero re nikan, kosi gbodo mo gbe ola fun ipinnu re. O si gbodo maa pese gbogbo okunfa dada ati ifokanbale fun pelu fi fi ife han si nibi imaa ba rerin, imaa ba sere, ati imaa se pelepele pelu re nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- to lo bayi pe:" eniti o pe julo ni igbagbo ninu awon olugbagbo ni eniti iwa re dara ju, eniti o si je eni esa ninu yin ni awon eni esa si awon iyawo won." Ibn Hiban ni o gba wa.
g. Imaa se suuru lori aburu re, ati imaa se atemora lori awon asise re, ati ima moo ri gbogbo asise re. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" Olugbagbo lokunrin kan koni binu si olugbagbo lobinrin kan, ti o (okunrin) ba korira nkankan ni ara re (obinrin), yoo ri nkan miran ti yoo yo ninu." Muslim.
h. Imaa jowu ati imaa se idabobo fun un, kogbodo maa ti lo si awon aye aburu ati ibaje. Olohun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا قُوا أَنْفُسَكُمْ وَأَهْلِيكُمْ نَارًا وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ"
Itumo:" Eyin olugbagbo ni ododo! E gba ara yin la, ati awon ara ile yin nibi ina ti o je awon eniyan ati awon okuta ni A fi ko o…" Suratu Tahrim: 6
i. Imaa so dukia re ti o dani, (oko re) ko gbodo mu ninu re ayafi pelu iyonda re, ko si gbodo se nkankan pelu re ayafi iyonu ati ifowo si re. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- sope:"Dukia mu'mini kan ko leto (fun elomiran) ayafi pelu iyonu re." Bayhaqi lo gba wa.
Eto awon Omo *
* Eto won nbe nibi sise amojuto isemi won, ati ini akolekan pelu alamori won, ati didide si itoju won, ati pipese oun ti won ni bukata si ninu jije, mimu, wiwo, ati ibugbe. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- so bayi pe:" O to fun omoniyan ni ese ki o se owo de ngbere si eniti o ntoju." Muslim.
* Ise esa awon oruko ti o dara fun won. Won gba wa lati odo Ojise Olohun-ki ike Re ma ba- ti o sope:" Won yoo pe yin ni ojo igbende pelu awon oruko yin ati awon oruko baba yin e ya so ara yin ni awon oruko to dara." Sahih Ibn Hiban:5818.
* Gbigbin awon iwa rere si inu okan won, gegebi itiju, ise aponle agbalagba, siso ododo, ifokantan, titele ase awon obi mejeji, ati bee bee lo.. ati igbe won jina si awon nkan aburu nibi awon oro ati ise gegebi iro pipa, ijanba sise, enini, ole jija, si se obi, ati bee bee lo. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" Olohun yoo bi gbogbo oludaranje nipa awon oun ti o daje se o so won, abi o rawon lare? Titi ti won yoo fi bi okunrin nipa awon ara ile re." Ibn Hiban:1636.
* Ki ko won ni eko ti o ni anfani ninu, ati rirewon ni rire ti o dara, ati sise asanya alabarin rere fun won. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" Gbogbo yin ni adaranje won yoo si bi yin nipa awon ti e da je, Imamu (asaju) adaranje ni i won yoo bi i nipa awon ti o da je, Okunrin adaranje ni i lori awon ara ile re won yoo bi i nipa awon ti o da je, obirin adaranje ni i ninu ile re, ohun na won yoo bi i nipa ohun ti o da je, omo-odo adaranje ni i lori dukia olowo re, won yoo bi nipa ohun ti o da je." Bukhari ati Muslim.
* Ini akolekan lori sise aseyori won pelu jijina si imaa se epe fun won. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so pe:" E ma maa se epe le ara yin lori, e ma maa se epe fun awon omo yin, e ma maa se epe fun awon dukia yin, toripe oseese ki e se konge lodo Olohun asiko gbigba re (fi ase si). Muslim:3009.
* Imaa se deedee laarin won, ati ima moo gbe ola fun apakan lori apakan nibi fifun, ati ebu. Bakanna nibi ibalopo pelu ike, toripe imo moo se deedee laarin won je okunfa sise obi ati ibinu ati ikorira laarin won. Lati odo Nu'man omo Bashir, o sope:" baba mi se sara fun mi pelu apakan dukia re, Iya mi-Umrah omo Rowaahat- ba sope: mi o ni (Olohun ki o yonu si) si titi ti Ojise Olohun yoo fi fowosi. Ni baba mi ba gbera lo si odo Annabi-ki ike Olohun ma ba- lati le fi jeri lori ebun mi. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ba sope: se gbogbo awon omo re ni o se eleyi fun? O sope: rara. (Ojise Olohun) o sope: e paya Olohun, " e si maa se dede laarin awon omo yin ". (Baba mi) O ba seri pada o si se adapada ebu na." Muslim:1623.
* Eto Alasunmo
Awon wonyi ni ara-ile okunrin ati awon alasunmo re, ati molebi re. Islam seni ni oju-oyin lori siso won po pelu owo ti o ba je olowo pelu imaa gbo bukata won ninu awon sara re ti o je oranyan ati asegbore, ati pelu dada nibi imaa beere nipa won, imaa se iwadi nipa won, imaa se pelepele pelu won, imaa kopa pelu won nibi ibanuje ati idunu won. Olohun so bayi pe:
" وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي تَسَاءَلُونَ بِهِ وَالْأَرْحَامَ "
Itumo:"…Ki e si beru Olohun Eniti e fi nbe ara yin ati okun ibi…" Suratu Nisaii: 1.
Islam ti se musulumi ni oju-oyin siso okun-ibi re po koda bi won ko soo po mo ara won, nitori oro Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ti o sope:" Ki i se oluso ibi po pelu se fun mi nse fun o (pelu so mi po, ma so e po), sugbon oluso ibi po ni eniti o sepe ti won ba ge ibi re e yoo sopo." Bukhari ni o gba wa.
Islam si ko imaa ge okun-ibi ati ima moo so po, o se eleyi ni okan ninu ese nla. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so pe: Olohun da eda, nigbati o pa ri dida okun-ibi ba dide (ni eniti nbeere ti si wa Olohun ni iso), Olohun ba sope: " o to ", o (okun-ibi) ba sope: eleyi ni aye iwa-iso lodo Re kuro nibi gige (okun-ibi). Olohun ba sope: " se o ni ni ife si pe ki n so eniti o ba so e po, ki nsi ge eniti o ba ge o ". o sope: be ni Ire Oluwa, Olohun ba sope:" eleyi ti wa fun o (ma se eleye fun o). Leyinna baba Huraerah ba ka oro Olohun to lo bayi pe:
فَهَلْ عَسَيْتُمْ إِنْ تَوَلَّيْتُمْ أَنْ تُفْسِدُوا فِي الأَرْضِ وَتُقَطِّعُوا أَرْحَامَكُمْ أُولَئِكَ الَّذِينَ لَعَنَهُمُ اللهُ فَأَصَمَّهُمْ وَأَعْمَى أَبْصَارَهُمْ
Itumo:" Nje e ha le ma reti pe ti e ba joga ki e wa ma se ibaje lori ile, ki e si ma ja okun ebi yin bi? Suratu Muhammad: 22. Bukhari ati Muslim lo gba wa.
* Eto Adaranje lori awon ti nda je (Eto olori lori awon omo eyin)
* Gbigbo ati titele ninu oun ti ko si iyapa Olohun nibe, itele ase re
 nigbati ko ba pa ase oun ti o je iyapa ase Olohun. Olohun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَأُولِي الْأَمْرِ مِنكُمْ "
Itumo:" Eyin olugbagbo lododo e tele Olohun, ki e si tele ti Ojise na, ati awon alase ninu yin…) Suratu Nisaii:56.
* Imaa se isiti fun un pelu pelepele ati imo moo se ijamba ati elenini re, eleyi pelu imoo to o nika si oun ti yoo se e ni anfani ati awon omo leyin re, ati imoo ran leti awon bukata awon omo leyin re. Olohun ti ola Re ga julo nso fun Musa ati omo iya re-Haroon- nigbati O ran won si Fir'aoon pe:
" فَقُولَا لَهُ قَوْلًا لَيِّنًا لَعَلَّهُ يَتَذَكَّرُ أَوْ يَخْشَى "
Itumo:" Ki eyin mejeji ba a soro ni pelepele, o le je pe yoo ronu tabi ki o beru" Suratu Taha:44.
* Wiwa pelu re e ni asiko ilekoko ati idaru-dapo, ati imo moo jade le lori i, ati jijina si riran an lowo ati iyepere re e, koda ko sepe ninu awon ijo ti ko se ijeje fun un. Nitori oro Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- to sope:" Eniti o ba wa ba yin, ti alamori gbogbo yin si sokan lori okunrin kan, ti o gbero lati tu akojopo yin, ki e pa." Sahih Muslim:1852.
* Eto Ara-ilu lori Adari
Ninu awon eto omo-eyin lori adari ni:
* Imaa se dogbandogba laarin won pelu ki o fun eleto ni eto re. O je dandan le lori dogbandogba nibi awon oranyan, ati nibi pipin awon iwo, ati nibi idajo. Gbogbo eniyan ni waju re deedee ni won, ko si ajulo fun enikan lori elomiran, ko si ireje fun ijo kan lori ijo miran, nitori oro Onse Olohun-ki ike Olohun ma ba- ti o sope:"Eniti iya re yoo le koko julo ni ojo igbende ni asiwaju alabosi". Tabarani ati Tayalisi.
* Imo moo se abosi, ireje, ati enini ara-ilu re. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe:" Eyikiyi eniti Olohun ba fi se oludari awujo kan, ti o wa ku ni ojo ti oku ni eniti o je olureje fun awon eniyan re ayafi ki Olohun O se alujanah ni eewo fun un." Bukhari ati Muslim.
* Imoo se ibani-jiroro pelu won nibi awon alamori ti o ni se pelu anfani ise-ilu, ajosepo awujo, ati eto-isuna. Ijiroro yi yoo ma waye nibi oun ti ko si itoka kan pato lati odo Olohun lori re. Bakanna imoo fun won ni anfani pelu ominira lati se afihan ati lati so ero won, ati imoo se atewogba awon ero wonyi nigbati anfani re fun gbo-gbo ba fi oju han. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" فَبِمَا رَحْمَةٍ مِنَ اللَّهِ لِنْتَ لَهُمْ وَلَوْ كُنْتَ فَظًّا غَلِيظَ الْقَلْبِ لَانْفَضُّوا مِنْ حَوْلِكَ فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاسْتَغْفِرْ لَهُمْ وَشَاوِرْهُمْ فِي الْأَمْرِ "
Itumo:"Nitori anu a ti odo Olohun wa ni iwo fi ro fun won, ibasepe o je oniwa buburu ati olokan-lile won ba ti tuka kuro lodo re, nitorina mojukuro fun won ki o si toro aforijin fun won, ki o si ma ba won jiroro nipa alamori na.." Suratu Aal-Imran:159.
* Ki o je pe ipile idajo ati iwe-ofin re eleyi ti yio fi ma se ijoba awon ara-ilu re je Shariah. Kosi aye fun irori ati ife-inu awon omo enia kan, ati awon idajo pelu ife-inu eleyi ti o se se ki o je asise, abi ki o se dede.
* Imo moo di ona mo awon ara-ilu, abi imo moo se moto-moto le won lori, ati imo moo mu alategun laarin re ati ara-ilu ti awon alategun yin won yoo ma yonda fun eniti won ba fe, ti won yoo si maa ko fun eniti won ba fe, nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- to so bayi pe:"Eniti o ba je oludari alamori kan ninu awon alamori awon musulumi ti o wa se gaga di won nibi awon bukata ati osi won, Olohun yoo se gaga di oun naa nibi bukata ati osi re ni ijo igbende."
* Imoo ke awon ara-ilu, ati imo moo la bo won lorun oun ti won ko ni ikapa re, abi imo moo funle mo won. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe:" Ire Olohun! Eniti o ba je oludari alamori kan ninu alamori ijo mi ti o wa le koko mo won, ba mi le koko mo oun naa, eniti o ba je oludari alamori kan ninu alamori ijo mi ti o wa se pelepele pelu won, Ba mi se pelepele pelu re." Muslim:1828.
* Eto Alabagbe (Aladugbo)
Islam pa ase sise daradara si alabagbe pelu itumo re ti o kun, nitori oro Olohun to so bayi pe:
" وَاعْبُدُوا اللَّهَ وَلَا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا وَبِذِي الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينِ وَالْجَارِ ذِي الْقُرْبَى وَالْجَارِ الْجُنُبِ وَالصَّاحِبِ بِالْجَنْبِ وَابْنِ السَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ مَنْ كَانَ مُخْتَالًا فَخُورًا "
Itumo:" E maa sin Olohun ki e si ma da nkankan po mo O, ki e si maa se rere si awon obi yin mejeji, ati awon ibatan ti o sunmo yin, ati awon omo-orukan, ati awon alaini, ati awon aladugbo ti o sunmo yin ati awon aladugbo ti o jina, ati awon ore alabarin, ati omo oju ona, ati awon ti owo otun yin ni, dajudaju Olohun ko fe awon onigberaga ati onifaari." Suratu Nisaii: 36.
O si se fifi arani aladugbo ni eewo yala pelu oro abi ise. Lati odo baba Huraerah-ki Olohun yonu si i- o sope: won so fun ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- pe: dajudaju arabirin kan ma ngba awe ni osan, o si ma nkirun ni orun, o si ma nfi ara ni aladugbo re pelu enu re e. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope: ko si oore ni ara re (obinrin na) ina ni iseri si re. Won tun sope: dajudaju arabirin kan ma nkirun oranyan, o si ma ngba awe ramadani, o si ma se saara pelu wara gbigbe die, ki i si fi ara ni enikankan pelu enu re. (Ojise Olohun) O sope: Al-jannah ni iseri si re e." Bukhari ni o gba wa ninu Al-Adab Al-mufrad.
Islam gbe ipo nla ati eto ti o tobi fun aladugbo. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" Jibril koye-kogbo ni eniti nso asotele fun mi nipa aladugbo ti ti mo fi nro pe yoo je ogun re e (mo fi ro pe Olohun se ipin fun aladugbo ninu ogun aladugbo re nigbati o ba ku u.) Bukhari ati Muslim.
O si se imo fi inira kan an ni oun ti o tako igbagbo. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- so bayi pe:" Mo fi Olohun bura pe ki i se olugbagbo, Mo fi Olohun bura pe ki i se olugbagbo, Mo fi Olohun bura pe ki i se olugbagbo. Won sope: Tani ire ojise Olohun? O sope: Eniti aladugbo re ko ni ifokanbale kuro nibi aburu re." Bukhari ati Muslim.
Gegebi o se ye lati moo se ifarada aburu re ati imoo se pelepele pelu re. Lati odo baba Huraerah-ki Olohunyonu si- o sope: arakunrinkan sope: ire Ojise Olohun! Dajudaju mo ni aladugbo kan ti ma nfi ara ni mi i, (Ojise Olohun) O sope: " ma lo, ki o si gbe nkan ini re jade si oju-ona", ni o ba lo o si gbe nkan ini re si oju-ona ni awon eniyan ba pe jo le lori, won ba nsope: ki ni nto de ba e? O ba sope: mo ni aladugbo kan ti ma nfi ara ni mi, mo ba fi ejo re sun Annabi-ki ike Olohun ma ba- O ba sope: ma lo ki o si gbe nkan ini re si oju ona" ni awon eniyan ba nsope: Ire Olohun! Ibi dandan re E ki o maa ba, Ire Olohun! Ma salai yepere re." ni iro ba de etigbo re (Aladugbo na) ni o ba wa ba a (arakunrin na), o ba sope: pada si ile re e, mo fi Olohun bura mi o ni fi ara ni o mo." Al-Adab Al-Mufrad.
Aladugbo ni awon eto koda ko mo je musulumi. Lati odo Abdillah omo Amr: Won pa ewure fun awon ara –ile re, nigbati o de, o sope: e fun alabagbe wa Yahudi, e fun alabagbe wa yahudi, e mi gbo ti ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe:" Jibril koye-kogbo ni eniti nso asotele fun mi nipa aladugbo titi ti mo fi nro pe yoo je ogun re e (mo fi ro pe Olohun se ipin fun aladugbo ninu ogun aladugbo re nigbati o ba ku u.) Bukhari ati Muslim.
* Eto Alabarin (Ore)
Islam seni ni oju-oyin nipa ini akolekan pelu alabarin, o si se awon eto kan fun ije-alabarin eleyi ti o leto pipe re fun ore (alabarin) nibi imoo se daradara ati imaa se isiti, nitori oro Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- to sope: Eniti o dara julo ninu awon alabarin lodo Olohun ni eniti o dara julo ninu won si alabarin re, eniti o dara julo ninu aladugbo lodo Olohun ti ola Re ga julo ni eniti o dara julo ninu won si alabagbe re." Tirimidhi ni o gba wa.
* Eto alejo
Ninu eto alejo ninu Islam ni ki won se aponle re, nitori oro Ojise Olohu-ki ike Olohun ma ba- ti o sope: "eniti o ba ni igbagbo ninu Olohun ati ojo-ikehin ki o ya moo se aponle aladugbo re, eniti o ba ni igbagbo ninu Olohun ati ojo-ikehin ki o ya mo se aponle alejo re nibi eye re (eye alejo)" o sope: ki ni eye re, Ire Ojise Olohun! O sope: osan kan ati oru kan, ati ise-alejo re fun ojo meta, oun ti o ba ye ni eyin eleyi je saara fun un, eniti o ba ni igbagbo pelu Olohun ati ojo-ikehin ki o ya mo so oro ti o dara abi ki o da ke." Bukhari ati Muslim.
Islam ka ise aponle alejo si kan ninu ise oloore. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- sope:" Ko si ninu omo-enia eniti o da bi arakunrin kan ti o mu ijanu esin ti o wa lo jagun si oju-ona Olohun ti o wa jina si aburu awon enia, ati bi okunrin kan ti o na ninu nkan ini re ti o si nse aponle alejo ti o si npe eto re e (alejo)." Imam Ahmad ati Al-Haakim ni won gba wa.
Gegebi o se je dandan lori alejo ki o se akeyesi ipo ati isesi eniti o gbaa ni alejo, ko gbodo gbe oun ti ko ni agbara re le lori, nitori oro Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ko leto fun musulumi kan ki o wa ni odo omo iya re titi yoo fi mu u da ese." Muslim lo gba wa. Itumo re nipe ko leto fun alejo ki o wa ni odo eniti o gba ni alejo leyin ojo meta titi yoo fi mu u da ese.
Eto awon Alaini*
Olohun ti O mo kanga-kanga se eyin fun awon eniti won ma nna oun ini won si oju-ona Re, awon eniti won ma ngbo bukata awon alaini ati awon oni-bukata pelu oro Re ti o sope:
" وَفِي أَمْوَالِهِمْ حَقٌّ لِلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ "
Itumo:" Won ma nmu ninu dukia fun eniti o toro ati eniti ko toro." Suratu Ad-dhariyaat:19.
Koda Islam ka awon sara ti omoniyan fun awon alaini si okan ninu awon oun ti o dara julo lati sunmo Olohun. Olohun so bayi pe:
" لَيْسَ الْبِرَّ أَنْ تُوَلُّوا وُجُوهَكُمْ قِبَلَ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَلَكِنَّ الْبِرَّ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَالْمَلَائِكَةِ وَالْكِتَابِ وَالنَّبِيِّينَ وَآتَى الْمَالَ عَلَى حُبِّهِ ذَوِي الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ وَالسَّائِلِينَ وَفِي الرِّقَابِ …"
Itumo:" Kii se daadaa ni ki e koju si iha gabasi ati iha yanma, sugbon oun ti o je daadaa ni eniti o gba Olohun gbo, ati ojo ikehin, ati awon Molaika ati tira na ati awon Anabi ati pe o fi owo tore nigbati oun naa ni ife si i (owo) (abi o tore nititori ife Re) fun alasunmo ati omo-orukan ati awon alaini ati omo ori irin-ajo ati awon atoroje ati fun irapada awon ti nbe ninu igbekun eru…" Bakorah:177.
O se ileri iya ti o le koko ni ojo igbende fun awon ti nko owo jo ti won ko pe eto Olohun ninu re. Olohun so bayi pe:
" وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلَا يُنْفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَبَشِّرْهُمْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ "
Itumo:"…Awon ti won nko wura ati fadaka jo ti won ko na si oju ona Olohun, nitorina fun won niro nipa iya eleta-elero." Suratu Taobah:34.
Nitori eleyi ni won fi se zakah yiyo ni oranyan ninu Islam, won si se e ni okan ninu awon origun ipile re, o si je oranyan lori gboogbo musulumi ti o ba ni odiwon (owo ti o wo) lowo ti odun kan si ti re koja lori re, nitori oro Olohun ti o sope:
" وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ وَذَلِكَ دِينُ الْقَيِّمَةِ"
Itumo:"Won ko pa won lase ju pe ki won josin fun Olohun, ki won se afomo esin fun Un, ki won si je olulodi si ijosin fun nkan miran leyin Re, ki won si ma gbe irun duro, ki won si ma yo zakah, eleyi ni esin ti o duro deedee." Suratu Bayinah:5.
Olohun ti ola Re ga julo se alaye awon ti o leto si (Zakat) pelu oro Re:
" إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاءِ وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ"
Itumo:" Ore (zakah) wa fun awon talika ati awon alaini ati awon ti nsise re (lati gba jo), ati awon ti okan won fa si Islam, ati fun irapada awon eru ati awon ti o je gbese ati si oju ona Olohun, ati omo oju-ona, oranyan lati odo Olohun, Olohun ni Olumo, Ologbon." Suratu Taobah:60.
Ikilo ti wa lati odo Olohun fun awon eniti won ko yo o (zakah) pelu oro Re:
" وَلَا يَحْسَبَنَّ الَّذِينَ يَبْخَلُونَ بِمَا آتَاهُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ هُوَ خَيْرًا لَهُمْ بَلْ هُوَ شَرٌّ لَهُمْ سَيُطَوَّقُونَ مَا بَخِلُوا بِهِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ "
Itumo:"Ki awon eniti won nse ahun pelu oun ti Olohun fun won ninu ola Re mase rope ore ni o je fun awon, oro kori be, aburu ni fun won, laipe ao fi oun ti won nse ahun re ko won lorun ni ojo igbende.." Suratu Aal-Imran: 180.
Aaye Ise ati Osise
 Ni aaye ise ati awon osise, Islam wa pelu awon onde ati awon opo eleyi ti o nse alaye ala ajosepo eniti o ni ise pelu awon osise pelu re, ati ajosepo won (awon osise) pelu re lati le so eto onikaluku awon mejeji, ati lati je ki ajosepo ti nbe laarin je ajosepo omo-iya ati ife, ki i se ajosepo oro ati ifi anfani di po ara won nikan.
Eto awon Osise
Islam pa ase pe ki ajosepo ti o wa laarin eniti o ni ise ati awon ti nbe labe ikapani re ajosepo omo-iya ati deedee fun aponle omoniyan, nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba-ti o lo bayi pe: Awon omo-iya yin je eniti won ba yin mojuto alamori yin, Olohun gbe won si abe ikapani yin, eniti omo iya re ba nbe labe ikapani re ki o ya fun je ninu oun ti o nje, ki o moo fun wo ninu oun ti nwo, ki e si ma la bo won lorun oun ti o ju agbara won lo, ti e ba pa won lase bee, e ya ranwo lowo." Sahih Al-Bukhari.
O se afirinle eto osise si owo-ise. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" Olohun sope: awon meta kan Emi ni ma je olutako won ni ojo igbende; okunrin kan ti o se adehun pelu oruko Mi leyinnaa ti o wa yapa, ati okunrin kan ti o ta omoluwabi ti o wa je owo re, ati okunrin kan ti o gba osise kan ti o si gba eto re ni owo re (o ba se ise re ti o gba fun un) ti ko wa fun ni owo ise re." Bukhari ni o gba wa.
Atipe Islam pa ase fi fun osise ni owo-ise ti o se ni kete ti o ba pari ise ti won gbaa fun un. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" E fun osise ni owo ise re ki aagun re o to gbe.: Sunan Ibn Majah:2443. Gegebi o se pase imo moo la bo won lorun oun ti o ju agbara won lo ninu ise, ti eleyi ba sele (ilabo won lorun ju oun ti o ju agbara won lo) o didan ki a ran won lowo pelu alekun owo ise won tabi pelu riranwon lowo pelu ara ni bi sise ise pelu won, nitori oro re-ki ike Olohun ma ba- ti o sope:"… ki e si ma la bo won lorun ohun ti o ju agbara won lo, ti e ba pa won lase bee,e ya ranwon lowo." Sahih Al-Bukhari.
Awon eto Oluni-ise (eniti oni-Ise)
Gegebi Islam ti bere lowo oluni-ise pe ki o se akiyesi eto awon osise be naa ni o bere lowo awon osise pe ki won se akiyesi eto oluni-ise pelu ki won se oun ti o fe lowo won ni ojuponna ti o dara julo lai ni abujenjeku, abi ilora ti o le ko aburu ba oluni-ise, nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ti o so bayi pe:"dajudaju Olohun nife si ti enikan ninu yin ba se ise ki o se daadaa." Sahih Al-Jami':1880.
Nitori ki won le se awon osise loju oyin lati se daadaa ati jijina si ireje nibi ise ti won yoo si so aponle ati iyi won, won se ere wonni eyiti o dara ju ninu ere nigbati won ba mo ise won dada ati de oju ami. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" eyiti o dara julo ninu ise ni ise owo nigbati o ba mo ise re daadaa." Sahih Al-jami':3283.
Awon Eto awon Eda miran ninu awon Eranko ati awon miran
Dajudaju Islam ko kewo kuru pelu sise afirinle eto fun omoniyan nikan, bi ki i sepe o se afirinle eto awon eranko naa, o si fun won ni awon eto eleyi ti o sepe o se se ki o sun eniti o ba se atetere pelu re de inu ina. Ninu awon eto yi:
Eto awon Eranko
Imoo fun won ni ounje je, ati jijina si imoo se ounje ati omi mole fun won titi won yoo fi ku. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- sope:"Won je obinrin kan ni iya nitori olongbo ti o ti mole titi o fi ku, ni o ba wo ina nitori re, ko fun ni onje je, ko fun ni omi mu nigbati o ti mole, ko si tu sile ki o ma je ninu kokoro ile." Bukhari ati Muslim.
1. Imoo se daadaa si won, eleyi pelu imo moo fi iya ati suta kan won, ati imoo gberu won oun ti won ko ni agbara re. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba-ti re koja pelu rakunmi ti eyin re ti papo pelu ikun re (niti ebi nla), O ba sope:"E beru Olohun lori awon eran osin yi ti won kole soro (lati so oun ti nse won ni ebi, abi ogbe), e si maa gun won nigbati won ba ni alafia lati gun, e si maa je won ni asiko ti ba ni alafia lati je."
2. Imo moo fi won se ere eleyi ti o le ko ipalara ati idiya je fun won, nitori oun ti won gba wa lati odo Ibn Umar ki Olohun O yonu si awon mejeji- pe o re koja pelu awon odomode lati iran kuraeshi ti won ba won fi idi eye kan mule ti won nta ni ofa. Ibn Umar wa sope:"Tani o se eleyi.? Ibi dandan Olohun (igbejina si ike Olohun) ki o ma ba eniti o se eleyi, dajudaju ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ti sebi le eniti o ba mu nkankan ti emi nbe ni ara re fun tita lofa."
3. Imo moo ya apejuwe (bu) pelu re, nitori oro Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ti o sope:"Ibi dandan Olohun ko ma ba eniti o ba ya apejuwe pelu eranko." Bukhari.
4. Imo moo seruba won, abi fi suta kan won. Won gba wa pe: awon wa pelu ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ni irin-ajo ni o ba jade lati se igbonse, ni aba ri eye kekere kan (gegebi eye ega) ti omo re (omo eye meji) wa pelu re, ni a ba mu omo re, ni o (eye na) ba de ti nfi iye re bo ile (gegebi pe on bo awon omo re), bayi ni ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ba de, o ba sope: tani o nseru ba eleyi (eye yi) pelu omo re, e da omo re pada fun un." O ri ile awon kokoro awurebe ti a ti sun ni ina, o ba sope: tani o sun eleyi ni ina, a ba sope: awa ni. O sope: ko leto (fun enikankan) lati je nkankan ni iya pelu ina ayafi Oluwa ina." Abu Dawood ni o gbaa wa ninu Tira "Adab Al-mufrad:295.
5. Islam pa ase nigbati a ba gbero lati se anfani pelu awon eran osin ti o je ti jije, ti a si se tan lati pa pe ki a se pelepele pelu re, a ko gbodo pon obe ni oju re, a ko gbodo pa ni oju awon eran miran, tabi ki won kan orun re siwaju ki o to ku. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" Olohun se sise rere lori gbogbo nkan ni oranyan, ti e ba pa nkan ki e maa paa daadaa, ti e ba dunbu nkan ki e dunbu re daadaa, ki enikookan yin pon obe re daadaa, ki o si se pelepele pelu oun ti o dunbu re.
Islam pa ase pipa apakan ninu awon eranko ati awon kokoro ti o le ko ipalara ba omoniyan, eleyi ri bee nitori ati se idabobo fun isemi omoniyan ti o lola ju isemi awon eranko ati awon kokoro yi, omoniyan ni aponle lodo Olohun ju won lo.
Ti o ba jepe awon eto yi wa fun eranko ninu Islam, ki wa ni ero re si awon eto omoniyan eleyi ti Olohun se agbega re lori gbogbo eda, O si se aponle re. Olohun so bayi pe:
" وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلًا "
Itumo:"Atipe dajudaju Awa se aponle fun omo Annabi Adam, Awa gbe won rin lori ile ati odo, Awa si nfun won ni ije-imu ninu awon oun ti o dara, Awa si da won lola ju opolopo ninu awon eda ti A da lo niti ola." Suratu Israi':70.
Ko pin lori sise ike fun awon eranko nikan, bi ki i sepe o se ike pelu won ni okunfa aforijin ese ati wiwo ogba idera (Al-jannah). Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe:" Laarin igba ti arakunrin kan nlo ni ona re ni ongbe ba ngbe, ni o ba ri odo (kanga) kan ni o ba so kale si inu re o si mu omi, leyinaa o jade ni o ba pade aja kan ti nyo enu re sita ti nsale je niti ongbe, ni arakunrin na ba sope: nipaapa ongbe aja yi ti de ipo ongbe ti o gbe mi i, ni o ba sokale si inu kanga naa ni o ba fi bata re pon omi leyinaa ni o ba fi enu re mu ni o ba fun aja naa ni omi mu ni Olohun ba dupe fun un, o si fi orijin. Won sope: ire Ojise Olohun se ao ma gba esan lori awon eran osin ni bi? (Ojise Olohun) O sope: beeni, nibi gbogbo edo tutu ni o ni esan (ni sise daradara si gbogbo eranko abemi ni esan wa fun.)
Eto igi ati Irugbin
Irugbin je oun ti Islam ti se ni eto fun omoniyan lati se anfani pelu eso re fun jije, o si se ni eewo gige re, abi ikoja-ala lori re laisi bukata ati laluri kan, koda o pase sise idabobo fun un, ati ifowosopo fun idagbasoke re ati pipo re. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:" Ti alukiyamo ba de ti o si wa ni owo ikan ninu yin igi ope kekere, ti o si ni agbara ati gbin ki o to dide ki o ya se bee." Bukhari ni o gba wa ninu Al-adab Al-mufrad.
Islam se gbigbin irugbin ati awon igi ti o dara ti won yoo se anfani ni ara re ni okan ninu ore ati sara eleyi ti won yoo san musulumi ni esan lori re. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- sope:" Eyikeyi musulumi ti o ba gbin irugbin kan, abi ti o ba lo ogbin kan ti eye, tabi enia, eran osin wa nje nibe ayafi ki o je sara (ore) fun." Muslim lo gba wa.
* Eto awon oju-ona ati oja
Islam gbe awon eto kan fun awon oju-ona ati awon oja. Ojise     Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope: E sora fun imoo joko ni awon oju-ona" Won sope: Ire Ojise Olohun! Ko si aburu fun wa nibi imoo joko nibe, a ma nse ijiroro nibe! Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- wa sope:" ti e ba ko ayafi ki e joko nibe, e ya fun ona ni eto re " Won sope: kini eto ona ire Ojise Olohun? O sope:" rire oju sile, kiko aburu (jijina si imo fi aburu kan enia ti nre koja), didahun salama, pipa ase dada, ati kiko ohun ti ko dara. Bukhari ati Muslim.
* Imoo mu kuro ni ona gbogbo oun ti o le pa olurekoja lara. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma a ba- sope:" Igbagbo (Eeman) pin si metaleladorin, tabi metalelogota ipin, eyiti o ni ola julo ninu re ni gbolohun (La illaha illa Lahu), eyiti o si kere julo ninu re ni imoo mu oun ipalara kuro ni oju-ona, atipe itiju ipin kan ninu igbagbo ni." Bukhari ati Muslim.
* Imo moo se ibaje awon oju-ona ati oja pelu awon oun ti awon eniyan ma nju si i ninu oun ti o je egbin. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope:"E beru awon nkan meji ti o le fa epe" Won sope: kini nkan meji ti o le fa epe ire ojise Olohun? O sope: eniti won yoo sepe fun ni eniti o bo si oju-ona awon eniyan, tabi abe boji won ti o si se igbonse si be." Muslim ati Abu Dawood ni won gba wa.
Dajudaju awon eto yi gbodo ni agbara ti yoo ma so, ti yoo si je amojuto fun un ati ti yoo si ma je awon eniyan nipa nibi sise amojuto re, toripe on be ninu awon eniyan eniti alamori re ko le duro sisin (bi o se ye ko wa) ayafi pelu ki o ni oun ti yo ma je nipa. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope: " Mo fi eniti emi mi nbe lowo re bura pe e o ma pa ase rere, e o si ma ko aburu, bi bee ko Olohun yoo gbe iya dide si yin lati odo Re, leyinaa e o ma pe E, ko si ni dayin lohun." Ahmad logba wa, Al-baani sope: o ni alafia.
*Awon oun ti o sopo mo awon eto ati awon oun ti o je dandan ni apapo.
Ni paapa Islam ti se ni oranyan fun musulumi ini akolekan pelu awon omo-iya re nibi-kibi ti won ba ri ki won wa, nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun-ma ba- ti o sope: apejuwe awon olugbagbo ododo nibi kike ara won, ati sise pelepele laarin ara won da gegebi ara kan ti o sepe ti okan ninu awon eya-ara re ba nke eto ero, gbogbo eya ara re yoku ni yoo maa ba ke eta-ero nibi airi orun sun, ati ara gbigbo na."
O pa ase sise ise lati tun alamori won se, ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- sope:" enikeni ninu yin koni di olugbagbo ododo (ni tooto) titi yoo fi ma fe fun omo-iya re oun ti o nfe fun ara re."
O si tun pa ase wiwa pelu won ni asiko ilekoko, ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba-sope:" olugbagbo ododo si olugbagbo ododo da gegebi ile ti apakan re sopo mo apakan, leyinna o wa le omo-ika re papo (lati se alekun alaye). Bukhari ati Muslim.
O pa ase imo se iranlowo ati ikunlowo fun won nigbati won ba ni bukata si. Olohun so bayi pe:
" وَإِنِ اسْتَنْصَرُوكُمْ فِي الدِّينِ فَعَلَيْكُمُ النَّصْرُ إِلَّا عَلَى قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ"
Itumo:"…Ti won ba si wa yin ni oluranlowo nipa esin, o je oranyan fun yin ki e ran won lowo ayafi lori awon ijo kan ti mojemu nbe ni arin yin pelu won, Olohun je Oluri oun ti e nse nise." Suratu Anfal:72.
O ko imoo se iyepere won. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba-sope:" omoniyan ko ni yepere musulumi kan ni aaye kan ti won ti nte iwo re mole ti won si nse iyepere omoluwabi re nibe ayafi ki Olohun o yepere re ni aaye kan ti o ti nife si iranlowo nibe, atipe omoniyan ko ni maa ran musulumi lowo ni aye ti won ti nyepere re ti won si nfi abuku kan omoluabi re ayafi ki Olohun ran an lowo ni aye ti o ti nife si iranlowo." Ahmad, ati Abu Dawood ni won gba wa, Al-bani sope " o dara" wo Sahih Al-Jami':5690.
Nitori ati se aabo fun awon eto omoniyan ni awujo Islamu ni Olohun fi sokale fun ojise re E awon ase eleyi ti yoo se ifirinle aabo fun awon eto naa ati jijina si mimoo fi suta kan an. Islam gbe awon ijiya kale fun fifi suta kan an, yala ijiya ile-aye eleyi ti won mo si huduud (Ala) ninu islam, tabi ijiya ti orun eleyi ti o wa nibi iya orun. Ninu awon ase ati awon ilana wonyi ni;
* Ileto dida oun ti o ba jeyo latara ise yi pomo ile-owo awon musulumi. Nipaapa ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ran arakunrin kan lati idile Al-Azd eniti won npe ni Al-Lutbiya lati loo gba owo zakah, nigbati o de, o sope: eleyi ni ti yin (eleyi ni owo zakah) eleyi ni won fun mi ni ebun. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope: ki lo mu ti ko joko si ile baba re, abi ile iya re, ki o wa reti pe se won yoo fun un ni ebun, abi won ko ni fun un, mo fi eniti emi mi wa lowo Re bura pe, enikankan ko ni mu nkan (ninu owo eleyi ti won bun nitori ise re) ayafi ki won gbe dide pelu re ni ojo igbende ti yoo gbe ko orun re, ti o ba je rakunmi to ni ohun rakunmi, abi malu ti o ni ohun malu, abi ewure ti o ni ohun ewure, leyinna ni o gbe owo re soke titi afi ri funfun abiya re, o ba sope: ire Olohun! nje mo je ise, ire Olohun! nje mo je ise, ire Olohun! nje mo je ise. Bukhari ati Muslim.
* Jije eewo sise ijamba pelu gbogbo aworan re, yala o je alafowo se ni gegebi nina tabi oun ti o joo, tabi pelu enu gegebi siso oro eniyan ni eyin re, iro pipa, eri eke, ati ebu bubu. Olohun so bayi pe:
"وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ بِغَيْرِ مَا اكْتَسَبُوا فَقَدِ احْتَمَلُوا بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا "
Itumo:" Atipe awon eniti won nni awon olugbagbo ododo lokunrin ati olugbagbo ododo lobinrin lara laije nipa oun ti won se, dajudaju won ru eru iro ati ese ti o han." Suratu Ahzab:58.
* Jije eewo sise aida pelu koko omoniyan ati kiko lu u. Olohun sope:
"وَلَا تَجَسَّسُوا "
Itumo:"…E ma se ma topinpin…"
Olohun tun so bayi pe:"
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَدْخُلُوا بُيُوتًا غَيْرَ بُيُوتِكُمْ حَتَّى تَسْتَأْنِسُوا وَتُسَلِّمُوا عَلَى أَهْلِهَا ذَلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ * فَإِنْ لَمْ تَجِدُوا فِيهَا أَحَدًا فَلَا تَدْخُلُوهَا حَتَّى يُؤْذَنَ لَكُمْ وَإِنْ قِيلَ لَكُمُ ارْجِعُوا فَارْجِعُوا هُوَ أَزْكَى لَكُمْ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ "
Itumo:" Eyin ti e gbagbo lododo! E ko gbodo wo awon ile kan ti kii se awon ile yin ayafi pelu iyonda, ki e si ki awon ara inu ile na, eleyi ni o dara julo fun yin ki e le se iranti. * Ti e ko ba ri enikankan ninu awon ile na, e ko gbodo wo titi won yoo fi fun yin ni iyonda, ti won ba si wi fun yin pe ki e pada, ki e yara pada, eleyi ni o dara julo fun yin, Olohun je Onimimo pelu ohun ti e nse ni ise." Suratu Nur:27-28.
* Jije eewo abosi pelu gbogbo ipin re, yala sise abosi omoniyan ni, abi sise abosi ara eni, nitori oro Olohun ti o sope:
"إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغْيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ (90) وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللَّهِ إِذَا عَاهَدْتُمْ وَلَا تَنْقُضُوا الْأَيْمَانَ بَعْدَ تَوْكِيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللَّهَ عَلَيْكُمْ كَفِيلًا إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ (91) "
Itumo:"Dajudaju Olohun npa ase sise deede, ati sise rere, ati fi fun awon alasunmo ni eto won, o si nko (fun ni) iwa ibaje, ati iwa ti okan ko, ati iwa tenbelekun, O nse ikilo fun yin ki e le ba gba ikilo * Ati ki e ma mu adehun Olohun se nigbati eyin se adehun, ati ki e ma si tu ibura leyin ti e ti ta koko re, e si ti mu Olohun ni eleri le ara yin lori, dajudaju Olohun mo ohun ti e nse ni ise." Suratu Nahl:90-91.
Olohun so ninu Hadith Al-Kudsi pe:" Eyin eru MI! E mi se abosi sise ni eewo fun ara MI, mo si se ni eewo laarin ara yin e ko gbodo se abosi.." Muslim.
Koda eniti o yapa sini ni adisokan ati ni esin, nigbati o sepe O se afirinle sise rere ati dada si won. Olohun so bayi pe:
"لَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُمْ مِنْ دِيَارِكُمْ أَنْ تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ "
Itumo:" Olohun ko ko fun yin nipa awon eniti won ko ba yin jagun nipa esin, ti won ko si le yin jade kuro ninu ile yin pe ki e se rere ati dede fun won, dajudaju Olohun nife si awon olusedede. Suratu Al-Mumtahinah:8.
* Sise bibu awon adisokan elomiran ni eewo nitori oun ti o le jade lati ara re nibi sise pasiparo eebu laarin awon iko mejeji, ati oun ti o le jeyo lati ara re nibi ikorira ati ibinu eyi ti yoo pepe losi ipinyeleyele ati jijina si ododo, nitori oro Olohun ti o sope:
"وَلَا تَسُبُّوا الَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ فَيَسُبُّوا اللَّهَ عَدْوًا بِغَيْرِ عِلْمٍ"
Itumo:" E ma se bu awon nkan ti won nsin leyin Olohun nitori ki won ma se bu Olohun niti abosi pelu aimokan…" Suatu Al-An'am:107.
O se afirinle iforojomitoro oro eyi ti o sepe erongba pelu re ni isalaye ododo pelu eko ati ladabi eleyi ti o pondandan titele re dipo eebu. Olohun so bayi pe:
" قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إِلَى كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ أَلَّا نَعْبُدَ إِلَّا اللَّهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِ شَيْئًا وَلَا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ "
Itumo:" Wipe: eyin oni-tira, (oni-tira majemu lailai ati majemu tutun) e wa sibi gbolohun oro-kan ti o dogba laarin wa ati laarin yin pe ki awa mase sin nkan miran bikose Olohun, ki awa ma si se wa orogun kan pelu Re, ki apakan wa mase mu apakeji ni Oluwa leyin Olohun; sugbon bi eyin ba pa eyin da, e wipe: E jeri pe Musulumi ni awa nse." Suratu Al-Imran:64.
* O se sise ibaje pelu gbogbo aworan re ni eewo ni ori-ile. Olohun so bayi pe:
وَلَا تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ بَعْدَ إِصْلَاحِهَا وَادْعُوهُ خَوْفًا وَطَمَعًا إِنَّ رَحْمَتَ اللَّهِ قَرِيبٌ مِنَ الْمُحْسِنِينَ "
Itumo:" E mase se ibaje lori ile leyin titunse re, ki e si pe E tiberu-tiberu ati ireti, dajudaju anu Olohun sunmo awon oluse-rere." Suratu Al-Araf:56.
* O ko ijeni nipa ninu esin, ati imaa je awon eniyan nipa lati yi adisokan won pada pelu agbara. Olohun so bayi pe:
وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ لَآمَنَ مَنْ فِي الْأَرْضِ كُلُّهُمْ جَمِيعًا أَفَأَنْتَ تُكْرِهُ النَّاسَ حَتَّى يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ "
Itumo:" Ti Oluwa re ba fe ni gbogbo eniti o wa lori ile ni o ba gbagbo ni ododo patapata, nje iwo yoo ma je awon eniyan nipa titi won yoo fi gbagbo?" Suratu Yunus: 99.
Eleyi ko tumo fifi ipepe si oju-ona Olohun ati mimu de etigbo awon eniyan pelu iwa rere ki won o le mo paapa esin islam sile, toripe ninu awon iroyin esin Islam ni jije dandan mimu de etigbo awon eniyan lapapo nitoripe o je esin agbaye ki i se esin ileto kan. Ki ipepe islam ti o ni Alafia de etigbo omoniyan ki o si mona losi ibi ododo wa lowo Olohun, eleyi ko si lowo omoniyan kankan.
* O pa ase imo se igbimoran, o si se nikan ninu awon opo ipile ninu ofin shariah (ninu ohun ti ko ba si eri fun ninu Al-Qur'ani abi Sunnah ti o mo ti o si ni alafia), eleyi ri bee nitori ki awon eniyan le maa gbadun ni awujo islam pelu awon eto won ti o ba ofin mu. Olohun so bayi pe:
" وَأَمْرُهُمْ شُورَى بَيْنَهُمْ "
Itumo:"…Atipe awon alamori won pelu igbimoran laarin won…" Suratu Shura:38.
Olohun se ojise Re ni oju-oyin lori lilo opo yi ki o le je oju-ona ti won yoo ma fi sise leyin re. Olohun sope:
" وَشَاوِرْهُمْ فِي الْأَمْرِ "
Itumo: "..Ki o si ma ba won jiroro nipa alamori na.." Suraatu Aal-Imran:159.
* O pa ase pipe awon eto fun awon ti o ni i, ati imaa se deedee laarin awon eniyan lapapo. Olohun so bayi pe:
إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَنْ تُؤَدُّوا الْأَمَانَاتِ إِلَى أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُمْ بَيْنَ النَّاسِ أَنْ تَحْكُمُوا بِالْعَدْلِ إِنَّ اللَّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُمْ بِهِ إِنَّ اللَّهَ كَانَ سَمِيعًا بَصِيرًا (58)
Itumo:" Dajudaju Olohun pa yin lase pe ki e da gbafipamo pada si odo awon ti o ni i, nigbati e ba dajo laarin awon eniyan e da a pelu dogba-ndogba, dajudaju Olohun dara ni Oluse ikilo, dajudaju Olohun je Olugboro Oluriran." Suratu Nisai:58.
* O pa ase riran eniti won bosi lowo koda ti riranlowo yi ba pepe fun lilo agbara. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" وَمَا لَكُمْ لَا تُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ وَالْوِلْدَانِ الَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْ هَذِهِ الْقَرْيَةِ الظَّالِمِ أَهْلُهَا …. "
Itumo: " Kilo se yin ti e yin ki yoo fi ja si oju ona Olohun ati fun awon alailagbara ninu awon okunrin ati awon obinrin, ati awon omode awon ti n wipe: Oluwa wa; mu wa jade kuro ninu ilu yi ti awon ara inu re je alabosi…" Suratu Nisai:75.
Ati nitoripe awon kan nbe ninu awon eniyan ti nkankan kole tun won se ayafi lilo agbara pelu won. O nbe ninu Islam awon ofin kan ti o je ti lilo agbara eleyi ti won yoo ma lo ni sise-ntele lati le se afirinle igbadun awon omo eniyan pelu awon eto yi ati lati le se akeyesi lilo re e, ati jijina si sise aburu pelu re, ati lilo idiya je eniti o ba se aburu pelu re. Ninu awon ofin yi ni;

Ofin ise idajo
Eleyi ni ofin ile-ise ti o da duro ninu ijoba Islam ti won yio ma pada si odo re lati le wa ojutu si awon ariyanjiyan ati ifarakanra laarin olupejo ati eniti a pe lejo, ati lati le gbe eto fun awon eniti o ni i, ati lati gbe dede duro ati lati le ko abosi ati lati le je olukoja ala ni iya ati lati kodi won labe lilo idajo Olohun ti o je pe Al-Kur'anu ati Sunnah Ojise Olohun ni ipile re le won lori, nitoripe awon mejeji (Al-Kur'anu ati Sunnah) ni ipile meji akoko ninu Islam fun idajo.
Wiwa ni ipo sise idajo ninu Islam ni awon mojemu ati awon onde ti o wa fun. Ninu awon mojemu ipile yi ni;
1. O (eniti yoo di ipo idajo mu) gbodo je oni-lakaye, ologbon, odo (ti o balaga), olumo otun yato si osi.
2. O gbodo je eniti o ni alafia ti o si pe ni eya ara ki o le ni anfaani lati se atemora eru idajo ati ilekoko re.
3. O gbodo je onimimo pelu ofin sharia, ki o si lese opinya eto (halal) kuro ninu eewo, ki o mo nipa awon oun ti o ruju laarin awon mejeji (halal ati eewo), ki o ni ikapa ati fun isele tuntun ni idajo ti o ti wa nile tele nitori afiwe to wa laarin won (kiyas), ki o si ni ikapa ati yo idajo lati inu tira Olohun (Al-qur'ani) ati Sunnah, ki o ni ikapa ati se idajo (fatwa) si awon alamori esin ati ti isemi aye.
4. Ki o je eniti o gba iroyin pelu awon iwa ti o dara ati iroyin rere, ki o si jina si awon iwa buburu, ki o si je eniyan rere ti awon eniyan ni ife si, ki won le ma gba idajo re pelu itelorun.
Gbogbo omoniyan ni awujo islam laifi ti esin, tabi adisokan, ati ipo re se ni o ni eto ipejo pelu pe ki o gbe edun okan, tabi ipejo re losi ile-ejo fun abosi ti o sele si.
Enikookan ninu olupejo ati eniti a pe lejo ni o ni eto si deedee ati dogbadogba lodo adajo. Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- so bayi pe:"Eniti won ba danwo pelu sise idajo larin awon musulumi, ki o ya se deedee laarin won nibi iwoye re (nibi wiwo oju re si olupejo ati eniti a pe lejo ti won wa ni waju re), ati nibi ami re (nibi sise ami pelu owo si awon mejeji), ati ni ijoko re (ki ijoko re wa ni ijina bakankanna si awon mejeji, ko gbodo fi si odo enikan ninu won), ko gbodo gbe oun re soke si enikan yato si enikeji."Sunanu Al-Bayhaqi, sugbon Hadith yi le. Ati nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ti o so fun Alli omo Abu Talib nigbati o ran ni adajo pe:" dajudaju Olohun yoo to okan re si ona ododo, yoo si fi enu re mona, ti awon meji (olupejo ati eniti a pe¬ lejo) ba joko lodo re, o ko gbodo se idajo larin won titi o fi gbo oro ni enu enikeji gegebi o se gbo ni odo eni akoko, dajudaju eleyi yio je ki idajo o han si yekeyeke." Sahih Ahmad ati Abu Dawood.
 Ipile ninu Islam ni bibora kuro nibi esun titi yoo fi rinle ni ododo, nitori oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- to so bayi pe:" ti o ba sepe won nfun omoniyan ni gbogbo oun ti o ba nbere ni (lai si eri ti o mule ni odo adajo), awon omoniyan o ba maa beere eje ati dukia omoniyan miran, sugbon o pondandan lori eniti nbeere eto kan ki o mu eri wa, ki eniti won si nbere eto lowo re na si bura (pe ko ni eto lowo o hun.) Bukhari ati Muslim.
Eleyi ntoka sipe won ko ni gba oro eniyan ninu oun ti npe ipepe re lasan bi ki se pelu eri ti o fese rinle, tabi ki eniti won pepe le lori gba pe bee ni.
O nbe fun eniti won fi esun kan ninu Islam awon eto, fifi esun kan ko tumo si pe ki won gba awon eto re ni owo re, ko si ijeni nipa, abi ijeni ni iya, abi pipe ni oni-ibaje, ati ideruba nitori wipe o se afirinle awon esun ti won fi kan. Ojise Olohun-kiike Olohun ma ba- so bayi pe:"dajudaju Olohun yoo je won ni iya awon eniti won ba nje awon eniyan ni iya ni ile-aye." Muslim.
Won gba wa lati odo Umar omo Al-khatab-ki Olohun yonu si- ti o sope:"ko si ifokanbale lori okunrin kan ti won ba fi ebi pa, tabi ti won ba deruba, tabi ti won ba ti mole wipe kole pa iro mo ara re (ki o le ba la kuro lowo iya)."
Ipenilejo ninu islam je ojuse ara eni, won ko ni je omoniyan ni iya nitori ese elomiran, ko leto sise atatapo esun, ati ijiya, tabi inira de odo awon alasunmo (molebi) ati omo eniti won fi esun kan. Olohun so bayi pe:
" مَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِنَفْسِهِ وَمَنْ أَسَاءَ فَعَلَيْهَا وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ (46) "
Itumo:"Enikeni ti o ba se ise rere, o se fun ara re, enikeni ti o ba si se ise buburu, o se fun ori ara re, Oluwa re kii se alabosi fun awon eru (Re). Suratu Fusilat:46.
Ati oro ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- ti o sope:"Eteti ki e gbo emikan ko gbodo gba esan lori omiran." An-Nasai lo gba wa.
Awon mojemu ati eko nbe fun sise idajo ninu Islam Iwe ti khalifa elekeji asiwaju onigbagbo ododo, Umar omo Khatab fi ranse si okan ninu awon adajo se alaye fun wa titobi akolekan islam si abala yi, eleyi ti ngbero pelu re ni ipo akoko idabobo awon eto awon omoniyan ni awujo islam.
Lati odo eru Olohun Umar asiwaju onigbagbo ododo losi odo Abdillah omo Koes-alafia Olohun ki o ma ba o, leyinaa dajudaju sise idajo je oranyan ti o kanpa, ati Sunnah ti o je titele, ki o gbo ejo ti won ba gbe wa si odo re dada ki o to se idajo, dajudaju ko si oore nibi ki o so idajo kan ti ko ni je lilo, moo se dogba-ndogba laarin awon eniyan nibi ijoko re, ki o ma ba gbe are fun enikan nitori ipo re , ki awon eniyan si le ma baa jakannu nibi sise deede re, eri je dandan lori olupe-ejo, ibura si je dandan lori eniti won pe lejo, sise atunse leto larin awon eniyan ayafi atunse ti o ba so eewo di eto, abi ti o so eto di eewo. ki ejo ti o da ni ana, ti o se ayewo ara re nibe ti won si fi o mona lo sibi imona, mo se kodi re lati pada losi ibi ododo.
Dajudaju ko si oun ti o le ba ododo je, ki o wa lo mo pe pipada si idi ododo loore ju titenpele lori ibaje, ni agboye oun ti nlo ti nbo ninu okan re, eyiti o je iyemeji ati royiroyi ninu oun ti ko si itoka kankan lati inu Al-Kur'an tabi Sunnah lori re, ki o si mo awon oun ti o jo ara won, leyinnaa ki o si mo fi awon alamori we ara won, leyinna ki o ma se amulo eyiti Olohun nife si ju ninu won, ati eyiti o sunmo ododo ju ninu iwoyesi re …"
Oro nipa sise idajo ninu Islan gun, o si ni awon iwe ti won kakun lori re, eniti o ba fe alekun oro ki o lo si inu won.

Ofin ise amojuto ati isiro
O je ofin esin asegbore. Erogba pelu re ni sise amojuto imulo ofin Olohun laarin awon eru Re labe ipepe si daadad ati kiko aburu, labe jije awon eniyan nipa lilo awon ofin esin, ati idiyaje eniti o ba se awon ise buburu ti o yapa si ofin Olohun, ati sise amojuto awon alamori ti o sopo mo isemi aye awon ara awujo gegebi ireje nibi rira-tita, ati tita awon oun ti o je eewo, ati kiko oja pamo ti awon eniyan si bukata si, bakanna ohun elo gbogbogbo, gegebi wiwo awon ile alapa ti o ti fee wo ni iberu aburu re lori awon ara awujo. Awon ise atinuwa wonyi ti ofin ise amojuto nse wonyi je amuse si oro Olohun ti ola Re ga julo to so bayi pe:
" كُنْتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَتَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ "
Itumo;" Eyin ni ijo ti dara julo ti won gbe dide fun awon eniyan, e npa won ni ase rere, e si nko awon iwa ibaje fun won…" Suratu Aal-Imran:110.
Atipe nitori iberu iya Olohun eyi ti O sope:
" لُعِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَى لِسَانِ دَاوُودَ وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ذَلِكَ بِمَا عَصَوْا وَكَانُوا يَعْتَدُونَ "
Itumo:" Won sebi le awon ti won se aigbagbo ninu awon omo Israila lati ori ahon Dauda, ati Isa omo moriyamo, eyi je be nitoripe won yapa si oro Olohun, won si je eniti won re koja enu-ala." Suratu Maida:78.
Nitorina o je dandan lori enikookan ninu awon awon enia awujo idide si ipepe losi bi rere ati kiko iwa ibaje pelu bi enikookan ba se ni agbara mo, nitori oro ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ti o so bayi pe: Enikeni ninu yin ti o ba ri ibaje kan, ki o yaa yi pada pelu owo re, ti ko ba ni agbara (ati se ayipada re pelu owo re), ki o ya se ayipada re pelu enu re, ti ko ba ni agbara eleyi, ki o se ayipada re pelu okan re, eleyi si ni eyi ti ole ju ni igbagbo." Muslim.
Ki o di mimo fun wa pe, yiyi iwa ibaje pada sopo mo mojemu pe ki ibaje ti o ju ibaje ti a fe se ayipada mo sele pelu re, eleyi ri bee nitori ki a le ri anfani ti a nfe nibi kiko ibaje.
Dajudaju esin Islam eyi ti Olohun fi ran ojise nla Muhammad-ki ike ati ola Olohun ma ba- eniti won fun ni ogbon ati oye- o se agbekale awon eto omoniyan si inu gbolohun kan ti o mo niwon, ti o si kun keke, Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- sope:"dajudaju eje yin, dukia yin, omoluwabi yin je oun owo laarin yin gegebi owo ojo oni (ojo Arafat), ninu osu yi, ninu inu yi…" Bukhari.
O nbe ninu oro yi eyi ti o po ninu awon eto omoniyan ti ofin sharia mu wa lati le se idabobo fun un, ati igbe iya lori eniti o ba fi suta kan awon eto yi. A o so ninu awon oun ti nbo alaye eleyi ti won se agbekale re ni ilu kairo nipa awon eto omoniyan ninu Islam. Ninu oun ti o ye ki a me nu ba nipe awon eto yi ti o waye ninu alaye yi waye ni awon opo odidi, eyi ri bee nitoripe awon eto yi ninu Islam sopo mo ara won ti o da gegebi ogiri ti apakan re sopo mo apakeji. N be labe awon opo yi awon etuntun ati eka, ti a ba fe so nipa won ao lo asiko ati igbiyanju ti o po pelu re, sugbon ao gba tito pelu sise itoka si won. Eniti o ba fe mo alekun nipa won ki o lo ka nipa won ni aye won. Atipe mo rope mi o koja ala ti mo ba sope dajudaju esin Islam wa lati so awon gbogbo eto patapata lati le so awon eniyan di olorire ni ile-aye won ati ni orun won.

Ikede Islam fun eto awon omoniyan
Ni Oruko Olohun, Oba ajoke aye Asake orun.
Olohun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِنْدَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ"
Itumo:"Eyin eniyan! Dajudaju A da yin lati ara okunrin ati obnirin, A si se yin ni ijo-ijo ati iran-iran ki e le ba mo ara yin, dajudaju eni aponle julo ninu yin lodo Olohun ni eniti o paya Re ju…" Suratu Hujuraat:13.
Dajudaju awon orile-ede ti won je eka ninu ijo apejo ti Islam pelu igbagbo won si Olohun Oluwa agbaye, Oluse-da gbogbo nkan, Olufun-ni ni gbogbo idera Eniti O seda eniyan ni ona ti o dara julo, O si se aponle re, O si se ni arole ni orile, O si fi ti si ni odo lilo ati atunse re, O si gbe ko ni orun awon ise oranyan t'Olohun. O si se ni irorun fun gbogbo oun ti nbe ninu sama ati orile patapata, ati pelu igbagbo si ifiranse Annabi Muhammad-ki ike ati ola Olohun ma ba- eniti Olohun ran pelu imona ati esin ododo ni ike fun gbogbo agbanla-aye, ati ni olutuni sile kuro ni oko igbekun eru, olupa awon osa ati awon onimototo re, eniti o se ikede dogbandogba laarin awon eniyan lapaapo, ko si ajulo fun enikan lori elomiran ayafi pelu ipaya Olohun, o si pa sise opinya ati ikorira re laarin awon eniyan ti Olohun se eda won lati ara emi-kan soso.
Niti bibere pelu adisokan ijosin fun Olohun nikan soso, eleyi ti Islam duro le lori, eleyi ti o pe gbogbo omo eniyan patapata pe won ko gbodo josin fun nkankan ayafi Olohun, won ko si gbodo fi nkankan wa orogun pelu Re, apakan won ko si gbodo mu apakan ni Oluwa leyin Olohun. Eleyi ni o je igbekale ipile pataki fun ominira omoniyan ati aponle won, o si se ikede ominira eniyan kuro ni oko eru fun omoniyan egbe re.
Atipe niti amuse oun ti ofin Sharia mu wa nibi sise amojuto fun esin, emi, lakayi, omoluwabi, owo, ati molebi, ati oun ti Sharia da yato pelu re, nibi jije ofin ti o se akotan gbogbo nkan patapata ati ni iwontun-wonsi nibi gbogbo ipo ati idajo re, o se akopo laarin emi ati ara, ati larin lakaye ati okan, ati niti kikanpa mo ojuse, asa ati itan ijo islam ti Olohun se ni ijo ti oloore julo ti o mu olaju agbaye wa fun omoniyan, eyi ti o se deede ti o si ro ile-aye po ma orun, o si se akopo laarin imo ati igbagbo, ati oun ti won fe ki ijo yi (ijo islam) se ni asiko yi lati se itosona fun omoniyan laarin ifaga-gbaga, ati mimu ona abayo wa si awon wahala eto oro isuna.
Ati niti ikopa ninu igbiyanju omoniyan nipa awon eto eniyan ti o sepe erongba pelu re ni iso omo eniyan kuro nibi imoo je anfaani re pelu bo se wu, ati ikanpa mo ominira ati awon eto re ti o se deede pelu ofin sharia ninu isemi aye.
Ati niti igbagbo pe dajudaju awon eto ipile ati awon ominira apapo ninu Islam je ipin kan ninu esin Islam ti enikankan ko ni agbara ati pare tabi ki o koo patapata tabi apakan ninu re, tabi fi abuku kan an, tabi pati si egbe kan, toripe o je idajo Olohun ti O se ni oranyan, ti O si so awon tira kale pelu re, ti O si gbe opin awon ojise eniti o fi pe awon ifiranse sama dide pelu re, ti sise akolekan pelu re si je ijosin, ti gbigbe jusile, tabi sise ibaje pelu re wa je aburu, oun si ni esin ti won yoo bi gbogbo omoniyan nipa re nikookan, ti yoo si bi ijo (Ummah) nipa re ni apapo. Dajudaju lori eleyi, awon ilu ti won je eka ninu ijo apejo ti Islam nse ikede awon oun ti nbo yi;
Oro kinni:
Omoniyan ni apapo je idile kan ti jije erusin fun Olohun ko won papo, ati jije omo fun Annabi Adam. Gbogbo omoniyan je ikan naa nibi ipile aponle ti omoniyan, ati nibi ipile ojuse laisi iyato laarin won yala latara awo, ede, eya, oselu, tabi awujo, pelu oun ti o yato si awon eleyi ninu awon oun ti o je akakun, dajudaju adisokan gidi ni o ma nse afirinle fun idagbasoke aponle yi ni ojupon-na pipe omoniyan.
Oro keji:
Dajudaju gbogbo eda ni apapo je ara ile-Olohun (Won je eniti Olohun nse amojuto won, ti O si npese arisiki fun won, ati oun isemi won, ati oun ti yoo se won ni anfani), atipe dajudaju eniti o je ololufe julo si Olohun ninu won ni eniti o nse anfani si ara ile re julo, atipe dajudaju kosi ajulo fun enikankan ninu won lori elomiran ayafi pelu ipaya Olohun, ati ise rere.
Oro keta:
* Isemi je ebun Olohun, o si je oun idabobo fun gbogbo omoniyan kookan, awujo, ati ilu kuro nibi gbogbo sise ibaje pelu re. Ko leto lati ta eje sile laisi okunfa ti o leto ninu ofin Sharia.
* Won se lilo awon okunfa ti o le fa iparun fun omoniyan ni eewo.
* Idaabobo fun itesiwaju isemi omoniyan titi di asiko ti Olohun ba fe je oranyan ninu ofin shariah.
* Alafia ara omoniyan ni idaabobo, kosi leto lati fi suta kan an, gegebi kose leto lati fi aburu kan an ayafi pelu idi ti o ni ese nle ninu sharia, ti ijoba si je alamojuto fun imuse eleyi.
Oro kerin:
Ni asiko lilo agbara tabi nkan ogun, ko leto lati pa eniti ko ba ko pa ninu ogun gegebi agbalagba, obinrin, ati omode. Eto itoju je dandan fun eniti o fara gbogbe ati alaare, ati eto ounje fun awon molebi, ibugbe ati oun wiwo, won si se mimoo se aburu pelu awon ti won ba pa ni oju-ogun ni eewo, o si tun je dandan ki won se asopo awon molebi ti ogun ti fon won ka.
* ko leto lati ma ge igi, abi lati ma ba awon nkan ogbin ati awon eran osin je, tabi lati wo awon ile gbe ati ile-ise ilu awon ota pelu nkan oloro bombu, tabi nkan miran ti o yato si i.
Oro karun:
Gbogbo omoniyan ni oni ominira re, ati sise amojuto masomilenu re ni oju aye re ati leyin iku re, osi je dandan lorun ijoba ati awujo lati se amojuto fun oku re ati isinku re.
Oro kefa:
* Ebi ni ipile fun imaa be awujo, sise igbeyawo si je ipile fun ebi, o si wa fun awon okunrin, ati awon obinrin eto lati se igbeyawo, ko si leto lati kodi won lati je igbadun awon eto yi pelu awon onde kankan ti okunfa re le je ara, awo, tabi ilu.
* O si je dandan lori awujo ati ilu lati mu gbogbo ohun ti o le kodi sise igbeyawo kuro ni ona, ki o si se ona sise re ni irorun, ki o si se idaabobo ati amojuto fun awon molebi.
Oro keje:
* Obinrin se dogba pelu okunrin nibi aponle omoniyan, o ni eto gegebi awon oranyan ti o gbodo pe won, o ni eto ije ara-ilu ati idaabobo nkan ini adani re, ati eto sise amojuto oruko re ati ebi re.
* Dandan ni fun okunrin lati gbe eto ina owo lori molebi ati ojuse sise amojuto re.
Oro kejo:
* Gbogbo omo nigbati won ba bi ni oni eto lori awon obi mejeji ati awujo, ati ilu nibi rire, kiko leko, ati amojuto ara, eko, ati ladabi, gegebi o se pondandan sise idaabobo oyun, ati iya ati funfun won ni itoju adayanri.
* O wa fun awon baba ati awon ti won wa ni ipo won eto lati se asanya irufe eko eleyi ti won ba fe fun awon omo won pelu sise akiyesi ohun ti o ma je anfani fun won ati fun ojo iwaju won labe ilana eko ati idajo shariah.
* Ohun nbe fun awon obi mejeji eto lori awon omo, o si wa fun awon alasunmo eto lori awon molebi won ni ibamu si ofin sharia.
Oro kesan:
- Wiwa ati kikoni ni imo je oranyan lori awujo ati ilu, o je dandan lori ilu lati pese awon ona ati irin-ise re (wiwa mimo), ati pipese orisirisi imo eleyi ti yoo mu anfani wa fun awujo, ti yoo si tun fun omoniyan ni agboye esin Islam ati paapa aye, ati lilo re fun anfani omoniyan.
* Ninu eto gbogbo omoniyan lori awon ile-ise eto eko, ile eko giga, ile-ise iroyin, ati omiran ni ki won mojuto kiko ni ni eko esin, ati isemi aye ni eko ti o pe, ti o se deede, ti yoo se alekun agbega re, ati igbagbo re si Olohun, ati aponle re si awon oun ti o je eto, ati oranyan.
Oro kewa:
Nigbati o je pe dandan ni fun omoniyan ki o tele ilana esin islam, esin adamo, nigbana ko leto lati maa lo ijeni nipa le lori, gegebi ko se leto lati maa lo ije talika re, tabi ije ole re, tabi ije alaimokan re lati yi esin re pada si esin miran, tabi lati s'eri re lo si ibi keferi.
Oro kokanla:
- Won bi omoniyan ni omoluwabi, ko leto fun enikankan lati mu ni eru, tabi yepere re, tabi lo agbara le lori, tabi lo anfani re, kosi ije eru fun enikankan leyin Olohun ti ola Re ga julo.
- Imunisin pelu gbogbo ipin re je eewo ti o ni agbara, o si wa fun omo ilu ti won wa ni oko imunisin eto ti o pe lati ni ominira kuro ninu oko imunisin, o si je dandan lori gbogbo awon ilu, ati omo ilu lati se ikunlowo lati ja kuro lowo gbogbo iran imunisin. O si je dandan lorun gbogbo omo-ilu eto ki o se amojuto ara re, ati awon nkan alumoni re.
Oro kejila:
O wa fun gbogbo eniyan ninu ofin sharia eto ominira lilo bibo, ati sise asanya aye ibugbe re ninu ilu re, tabi ni ilu miran, o si ni eto lati ko lo si ilu miran nigbati won ba fun le mo ni ilu re, o si je dandan lorun ilu ti o lo lati se idaabobo fun un, ti o ba ti sepe okunfa kiko lo sibe ni iwa ase ninu ofin sharia ti o hu.
Oro ketala:
Pipese ise je eto oranyan lorun ilu ati awujo fun gbogbo eniti o ni ikapa ati se ise, omoniyan si ni ominira lati se asanya ise ti o ba bamu ti yoo se anfani fun un, ati fun awujo. Osise ni eto si ifokanbale, aabo ati gbogbo atileyin awujo miran. Kosi leto lati labo lorun oun ti ko ni agbara re, tabi jee nipa, tabi lo anfani re, tabi fi suta kan an, o si ni eto si ki o gba owo ise ti o se deede ise ti o se ni kiakia, o si leto si agbega ati ipo eleyi ti o ba to si. Won si fe ki o se afomo ise fun Olohun, ki o si see daradara ati bi o ti ye. Ti osise ati eniti o ni ise ba nse ariyanjiyan, o je dandan fun ijoba ki o da si lati ba won pari ariyanjiyan naa, ati lati mu abosi kuro nibe, ati lati fi ododo rinle, ati lati pa ase deede laisi ireje.
Oro kerinla:
Gbogbo Omoniyan ni o ni eto lati se akojo awon oro ti o ba ilana ofin sharia mu, o si gbodo jina sise afipamo oun ti awujo ni bukata si, tabi ireje, tabi ifi aburu kan ara re, tabi kan elomiran, atipe owo ele naa je eewo ti o ni agbara.
Oro keedogun:
Gbogbo omoniyan ni o ni eto lati ni dukia ni ibamu si ilana ti o ba sharia mu, ati lati maa lo anfaani awon eto ini dukia ti ko le ko ipalara ba a, elomiran, tabi awujo. Kosi leto lati gba dukia re kuro lowo re, ayafi nigba ti o ba di oranyan lati gbaa fun anfani gbogbogbo ninu awujo, ti yoo si je dida pada fun un laifi asiko foso.
Won se gbigba dukia eni ni eewo ayafi pelu okunfa ti o ba ofin sharia mu.
Oro kerindinlogun:
Gbogbo omoniyan ni o ni eto si sise anfani pelu awon ere ise owo re, eko re, tabi imo ero. O si ni eto si sise idaabobo fun anfani eko ati owo eleyi ti o je ere latara ise ti o se, pelu pe ki oun ti o se yi ma yapa si idajo sharia.
Oro ketadinlogun:
Gbogbo omoniyan ni o eto si imaa gbe ni ayika ti o mo kuro nibi gbogbo aburu ati aisan eleyi ti yoo je ki ara re wa ni pipe. O si je dandan lorun awujo ati ijoba lati pese eto yi fun un.
- O je dandan lori awujo ati ijoba lati pese eto ise amojuto ilera awujo pelu pipese gbogbo awon oun ti awujo ni bukata si fun won ni ibamu si ikapa re.
- O je dandan lori ilu lati pese eto igbese aye alafia fun eni kookan ni oun ti yoo to ati awon ti nbe ni abe itoju re. Eleyi ko ipese oun jije, oun wiwo, ibugbe, eko, iwosan ati gbogbo awon oun ti omoniyan ni bukata si sinu.
Oro kejidinlogun:
- Gbogbo omoniyan ni o ni eto si igbe aye alafia lori ara re, esin re, ara-ile re, omoluwabi re, ati dukia re.
- Enikookan ni o ni eto lati maa da se alamori isemi aye re ninu ile re, ati molebi re, ati dukia re, abase re. Ko leto ki a topinpin re, tabi lati maa fi aburu kan oruko re. O si je dandan lati se idaabobo fun un kuro nibi gbogbo abosi ati ikoja-ala.
- Ibugbe ni owo tire ni gbogbo asiko, ko leto lati wo inu kan pelu ayafi pelu iyonda awon ara ile naa. Ko leto lati da ile kan wo, tabi gbaa, tabi le awon ara ibe kuro.
Oro kokandinlogun:
- Gbogbo eniyan deedee ni won je niwaju ofin, oludari ati eniti won ndari bakana ni won se ri ni abala yi.
- Eto siseri lo si ile-ejo wa fun gbogbo awujo lapaapo.
- Kosi ese ati ijiya fun enikankan ayafi pelu idajo sharia.
- Eniti won pe lejo je alaise titi ipelejo yoo fi idi re rinle, pelu idajo ododo ti yoo se afirinle gbogbo ona lati se atileyin fun un.
Oro ogun:
- Ko leto lati kodi omoniyan tabi fi onde de ominira re, tabi je e ni iya lai nidi ninu ofin sharia. Ko leto lati jee ni iya ara, emi, tabi fi eyikeyi iran iyepere kan an, tabi se oun ti o le ko abuku ba aponle re.
- Ko leto lati te ori enikankan ba fun sise igbidanwo ilera, tabi ise ayafi pelu iyonu re, ati pelu majemu pe ko ma si ewu nibe fun ilera ati isemi re, gegebi ko se leto lati se agbekale awon ofin eleyi ti yoo yonda re fun awon ti won ba wa ni ipo lilo ofin.
Oro elekokanlelogun:
Gbigba oun-idogo je eewo fun omoniyan ni gbogbo iran ti o pin si ati nitori eyikeyi erogba.
Oro elekejilelogun:
- Enikookan ni o ni eto lati so oun ti nbe ninu lakaye re nigbati ko ba ti tako awon ofin ipile sharia.
- Enikookan ni o ni eto lati pepe si rere ati lati ko aburu ni ibamu si awon ondede ofin sharia.
- Igbohun si afefe oun pataki loje fun awujo. Lilo o si ona ti ko dara, tabi imo fi enu abuku kan awon Annabi, tabi lilo o si ibi gbogbo oun ti o le fa abuku ba oun rere, tabi ti o le fa aburu fun awujo, tabi adiokan je eewo.
- Ko leto lati ma se oun ti o le fa ikorira ijo kan, ati gbogbo ohun ti o le ma fa eye-meya nigbogbo ona.
Oro eleketalelogun:
- Ise ijoba lori awon eniyan je oun igba fi pamo. Sise ibaje ninu re, ati lilo o bikose ye je eewo ti a kan pa mo lati le so awon eto ipile fun omo eniyan.
- Enikookan ni o ni eto kikopa nibi idari awon alamori apapo fun ilu re, ni ikopa ti o han, tabi ni ona ekoro, gegebi o se ni eto lati wa ona ti yoo gba de ibi awon ise apapo ilu nibamu si ilana ofin sharia.
Oro elekerinlelogun:
Gbogbo awon eto ati ominira ti o rinle ninu ikede yi je ohun ti o
gbodo wa ni ibamu si idajo ofin sharia.
Oro elekarunlelogun:
Ofin sharia ni ibuserisi kansoso lati se alaye eyikeyi oro ninu awon oro ti o wa ninu ikede yi.
Al-Cairo: 14/1/1411, ti o se dede 5/8/1990.

Dajudaju ise ifirinle awon eto yi ni ona pataki lati gbe awujo islamu ti o yanranti dide, awujo ti yoo gba iroyin pelu awon oun ti nbo wonyi;
- Awujo ti o jepe omoniyan ninu re bakan-naa ni won, kosi ola ati iyato fun enikan lori elomiran latara ipile, eya, awo, tabi ede.
- Awujo ti o sepe dogban-dogba ni o je ipile igbadun re, pelu awon eto ati ilaborun ti o je oranyan. Dogbandogba ti o sepe o pile latara okansoso ipile omoniyan. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَى"
Itumo:" Eyin eniyan! Dajudaju A se eda yin lati ara okunrin kan, ati obinrin…"
Atipe ninu ike Oba-Aseda ti O se fun omoniyan ni aponle. Olohun so bayi pe:
وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلًا.
Itumo:" Atipe dajudaju A wa se aponle fun awon omo Annabi Adamo, A gbe won rin lori ile ati odo, A si nfun won ni ije-imu ninu oun ti o dara, A si se ajulo fun won lori opolopo eda ti A da ni ajulo." Suratu Israi:70.
- Awujo ti o sepe ominira omo eniyan se deede pelu itumo isemi aye re, won bi pelu re ti yoo si maa semi ninu re, ti yoo si ni ifokanbale kuro nibi idaamu, ijegaba, iyepere, ati imunisin.
- Awujo ti yoo ni akolekan awon eniyan re, ti yoo si pese gbogbo okunfa idurosinsin ati idagbasoke fun won.
- Awujo ti o sepe oludari ati eniti won nda bakannaa ni won niwaju ofin ti Oba-Aseda gbe kale laisi ajulo, tabi iyato.
- Awujo ti o sepe agbara ninu re je oun gba fi pamo ni orun adari, ki o le se amuse awon oun ti ofin sharia la kale ninu awon asunta, ati ilana ti o gbe kale ki awon asunta yi le di amuse.
- Awujo ti gbogbo eniyan inu re yoo ni igbagbo pe dajudaju Olohun ni Oluni gbogbo aye patapata, atipe gbogbo oun ti nbe ninu re je oun ti won se fun anfani awon eda Olohun lapaapo, ti o si je ebun lati odo Re lai jepe enikankan leto si ju enikeji lo. Ninu eto omo-eniyan kookan ni ki owo re te ipin ti o se dede ninu ebun Olohun yii. Olohun so bayi pe:
" وَسَخَّرَ لَكُمْ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مِنْهُ "
Itumo:" Atipe O ro fun yin gbogbo oun ti o wa ninu awon sama ati ile patapata lati odo Re.." Suratu Jathiyah:13.
- Awujo ti awon ofin iselu ti o nse amojuto awujo fese rinle ninu re, ti awon oludari re si nse amulo awon ofin naa pelu gbigba imoran. Olohun so bayi pe:
وَأَمْرُهُمْ شُورَى بَيْنَهُمْ
Itumo;" Atipe alamori won pelu imoran laarin won ni.."
- Awujo ti o sepe gbogbo awon anfaani ti o se deedee wa ninu re, ki enikookan ninu re le mu awon ojuse ti o se deede agbara re, ti won yoo si se isiro re le lori niwaju ijo re ni ile aye, ati ni odo Olohun ti o ba di ni orun. (Gbogbo yin ni adaranje, won yoo si bi yin leere nipa awon oun ti e da je) Bukhari ati Muslim.
- Awujo ti oludari ati awon omoleyin yoo duro ni iwaju ile-ejo bakan naa, koda to fi de ori awon eto idajo.
- Awujo ti o sepe enikookan ninu re je nkan pataki ninu awujo, ti o si sepe ninu eto re ni ki o pe ejo lori eyikeyi eniti o ba se iwa aidara si awujo. O si leto ki o wa iranlowo lodo elomiran, ki awon elomiran naa si ran an lowo ninu ipepe re ti o je onideede.
- Awujo ti o tako gbogbo ikoja-ala patapata, o si se afirinle ifokanbale, ominira, aponle ati deedee, pelu idunnimo oun ti ofin Olohun fi rinle fun enikookan ninu eto, ati sise ise lori lilo re, ati sise igbiyanju lati daabo boo.
Dajudaju awon eto ti a so siwaju yi ninu alaye ti o lo je eyiti a yo lati inu Al-kur'ani Alaponle ati Sunnah abiyi ti Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- yala Sunnah ti oni oro ni, tabi ti ise, tabi alafirinle. Ki o di mimo pe awon eto ti a toka si koja yi je awon eto apapo ati awon opo ti o ko opolopo alaye sinu ti a ko menu baa nitori ki a ma baa fa oro gun, sugbon ni ibamu si oun ti a so ninu oro keedogun pe ofin sharia ni ibuserisi kan soso fun alaye eyikeyi ninu awon oro ti o waye ninu ikede na.

Iroyin awon eto omoniyan ninu ofin shariah
* Dajudaju o je eto ati ebun Olohun, ki i se ebun lati odo omoniyan eyi ti yoo wa labe ife-inu, erogba, ati fun anfani ti arare.
* Dajudaju o je eto ti o sopo mo adisokan esin Islamu, ti won se aabo fun un pelu idajo Olohun. Ikoja ala lori re tumosi ikoja ala lori omoniyan ati ikoja-ala lori idajo Olohun eleyi ti yoo fa idiyaje orun gegebi yoo se fa idiyaje aye.
* Dajudaju o je eto ti o kun fofo ti o se deede pelu adamo omoniyan, ti o tun se deede pelu abimo re, ti yoo si ma se akiyesi re gegebi omoniyan nibi ini agbara ati ije ole re, ati ni igba nini ati aini re, ati ni igba aponle ati iyepere re.
* Dajudaju o je eto fun enikookan ti o ba wa labe ofin idajo islamu laifi ti awo, ilu, esin, ede, tabi ipo re ninu awujo se.
* Dajudaju o je eto ti o fi idi mule ti ko si le yi pada, pare, tabi baje ni eyikeyi asiko tabi aaye, yala lati odo enikookan ni tabi awujo.
* Dajudaju o je eto ti o se afirinle gbigbe awujo kan dide ti gbogbo eniyan kookan ninu re yoo maa je igbadun isemi alaponle pelu irorun, nitoripe o je ike lati odo Oluwa agbanlaye fun gbogbo eniyan patapata. Yoo maa ba won se amojuto awon eto won gegebi eto iselu, eto isuna, eto awujo, ati ti iwa.
* Dajudaju o je eto ti o ni onde, ki i se eyi ti ko ni ijanu, nibi pe kogbodo tako ipile ofin sharia tabi fi aburu kan awujo. Ni apejuwe ominira siso ododo ati gbigbe ogun dide si ibaje, ati sise iranti fun gbogbo eniyan nibi oun ti yoo se awujo ni anfani wa fun gbogbo eniyan yala lori alamori aye ni, tabi alamori esin, sugbon ominira yi je eyiti won de ti won ko tu sile nitori ki omoniyan ma baa si lo. Awon ala kan wa ti ko leto lati re koja ayafi ki ibaje ko fonka, ala Olohun yoo si di oun iteloju, aburu yoo si kari gbogbo eniyan. Ninu awon onde yi ni;
1. Mimaa lo ominira yi pelu ilana eko eleyi ti o duro lori sise ijiroro pelu ogbon ati waasi ti o dara, ti o jina si ijeni-npa eleyi ti o le fa wahala ati idamu ti ko si ni mu anfani wa rara. Olohun so bayi pe:
" ادْعُ إِلَى سَبِيلِ رَبِّكَ بِالْحِكْمَةِ وَالْمَوْعِظَةِ الْحَسَنَةِ وَجَادِلْهُمْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنْ ضَلَّ عَنْ سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ
Itumo:" Pe ipe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ati waasi ti o dara, ba won jiyan ni ona ti o dara, dajudaju Oluwa re mo nipa eniti o sina kuro ni oju ona Re ju, O si mo julo awon eniti won mona." Suratu Nahl:125.
2. Mima se ifanfa nipa awon alamori ti o sepe ifenuko wa lori won ti awujo Islam si ni igbagbo si i, gegebi bibe Olohun, ati ododo Anabi Muhammad-ki ike Olohun ma ba- ati gbogbo oun ti o le fa suta ati abuku ba Islam ati awon musulumi.
3. Mima maa lo ominira si oun ti o le fa aburu fun omoniyan yala nibi awon alamori esin won ni tabi alamori ile-aye won, gegebi mimaa ba omoluwabi won je, tabi mimaa tan koko won ka, tabi mimaa da si oun ti o le je okunfa titan aburu ati ibaje kale. Olohun so bayi pe:
" إِنَّ الَّذِينَ يُحِبُّونَ أَنْ تَشِيعَ الْفَاحِشَةُ فِي الَّذِينَ آمَنُوا لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Itumo:" Dajudaju awon ti won nife si mima tan ibaje ka nipa awon olugbagbo ododo, iya eleta-elero nbe fun won ni aye yi ati orun, Olohun mo sugbon eyin ko mo." Suratu Nur:19.

Awon Iruju ti won nso nipa awon eto omoniyan ninu Islam:
Iruju Akoko:
Dajudaju sharia islam eleyi ti won so kale fun Annabi Muhammad-ki ike Olohun ma ba- lati bi egberun ati irinwo odun seyin de eto omoniyan mole, toripe awon eto wonyi, ninu igbagbo won, wa ni oborogidi ti ko si si fun un idagbasoke ti o le se deedee idagbasoke olaju ti o wa laye nipa oun elo omoniyan eleyi ti idagbasoke nba ni ibamu si bi asiko se nlo siwaju si.
Esi si iruju yi:
Islam yato si awon esin sama miran ti o siwaju re, awon ti o jepe won nse amojuto emi omoniyan nikan ni abala ajosepo re pelu Oluwa re, nigba ti o si jepe ofin sharia islam je ofin ti o pe, nitoripe o nse amojuto esin ati aye. On se amojuto esin nitoripe on se amojuto ajosepo eru pelu Oluwa ati Oluseda re, o si tun je ofin aye nitoripe on se amojuto ajosepo laarin awon ara awujo musulumi ati ajosepo won pelu awon elomiran ninu awon eniyan. Pelu eleyi o fihan pe ko ri bi awon esin sama yoku ti o siwaju re, ti won so kale fun asiko kan pato, fun awujo kan pato gegebi esin yahudi ati nasara, sugbon Islam so kale fun gbogbo eniyan. Olohun so bayi pe:
" وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ "
Itumo:" A wa ko ran nise ayafi ki o le ba je ike fun gbogbo aye ". Suratu Anbiyah:107.
Nitorina, dajudaju eniti o ba woye si idajo ofin sharia yoo ri pe eka meji ni oni;
* Eka alakoko: eleyi ni eyiti nse amojuto ajosepo eru pelu Oluwa re nibi adisokan, igbaagbo, ijosin, ati ogun pinpin. Eleyi ni awon idajo ti o fi ese mule ti kosi si aye fun sise igbiyanju lori re tabi ki a yii pada yala pelu alekun ni tabi ipare ni eyikeyi asiko, aaye, tabi ipo. Eleyi si ni a ma npe ni oun ti a juwo juse sile fun un ti o si fi ese mule gegebi; irun kiki ni apejuwe, origun re ati onka raka re fese rinle, bee naa ni zakah yiyo, odiwon re fese mule, bee si tunni awon ti yoo je ogun won je eniti a mo ti won ni onka ati odiwon ti yoo to si enikookan, bayi naa sini gbogbo oun ti o ba niise pelu ijosin miran.
* Eka elekeji ni eyiti nse amojuto awon ajosepo laarin awon eniyan, apakan pelu apa-miran ninu awon ajose eleyi ti o niise pelu awon alamori aye won ati ajosepo won pelu elomiran ninu awon awujo. Eleyi idajo sharia wa lori re ni odidi ti won ko foo si wewe, nitori ki o ma baa gba atunse labe sise igbiyanju ti yoo mu anfani wa fun awujo ati omoniyan ni gbogbo asiko ati aaye, ki o si le maa ba idagbasoke eleyi ti o nsele latara idagbasoke awujo mu, gegebi ofin ijiroro eleyi ti o wa ninu sharia ni odidi laifo si wewe. Kosi eri kan pato ti o se alaye ona lilo re, eleyi ri bee ayafi nitori ki aaye le wa fun sise igbiyanju ti yoo mu anfaani apapo wa fun enikookan ati awujo ni ibamu si awon oun ti asiko ati aaye kookan ba ni bukata si, nitori oun ti o se igba kan ni anfaani, o sese ki o ma se igba miran ni anfaani. Eleyi je oun ti nse itoka lori pe ofin sharia islamu je ofin gbogbo agbaye, eyiti o dara fun gbogbo asiko ati gbogbo aaye.

Iruju elekeji:
Eniti ko mo paapaa Islam tabi ti o gba eko nipa Islamu lodo awon ota esin ma nso pe Islamu ma nse abosi awon ijo ti o ba yapa si, ki i gboju wo eto won, eleyi si tako ilana eto omoniyan ti o se afirinle ominira adisokan fun enikookan.
Esi si iruju yi:
Dajudaju ipo ofin sharia Islamu si awon eniti won yapa si ni adisokan ninu awon ijo miran je oun ti o han ti ko si si nkankan ti o pamo ninu re. Lati ara awon itoka Al-Qur'an ati Ahadithu ojise Olohun alaponle yoo han si wa pe dajudaju ominira esin ni awujo islamu wa fun gbogbo eniyan, ko leto fun ilu islamu lati je elesin miran nipa ki o wo inu islamu ni ibamu si oro Olohun ti ola re ga julo to so bayi pe:
" وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ لَآمَنَ مَنْ فِي الْأَرْضِ كُلُّهُمْ جَمِيعًا أَفَأَنْتَ تُكْرِهُ النَّاسَ حَتَّى يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ "
Itumo:" Ti Oluwa re ba fe ni gbogbo eniti won wa ni orile ni won o ba gbagbo patapata, se iwo o ma je awon eniyan nipa titi won yoo fi gbagbo ni?". Suratu Yunus:99.
Ajosepo pelu won je oun ti o leto, jije ounje awon eniti won fun won ni tira (Yahudi ati nasara) je eto, koda islamu gbojuwo oun ti o koja eleyi pelu pe o se fife ninu awon eniti won fun won ni tira (yahudi ati Nasara) ni eto. Kosi iyemeji pe sise igbeyawo ati kiko ebi jo je okan ninu awon oun ti islam ni akolekan re, pelu eleyi o se fife ninu won ni eto, nitori oro Olohun to so bayi pe:
" وَطَعَامُ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ حِلٌّ لَكُمْ وَطَعَامُكُمْ حِلٌّ لَهُمْ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الْمُؤْمِنَاتِ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ "
Itumo:"…Ati ounje awon eniti A fun ni tira leto fun yin, ounje ti yin na si leto fun won, ati awon obinrin omoluwabi ninu awon olugbagbo lododo lobirin ati awon obirin omoluabi ninu awon ti A fun ni tira…" Suratu Maida:5.
Olohun tun so bayi pe:
" إِنَّمَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ قَاتَلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَأَخْرَجُوكُمْ مِنْ دِيَارِكُمْ وَظَاهَرُوا عَلَى إِخْرَاجِكُمْ أَنْ تَوَلَّوْهُمْ وَمَنْ يَتَوَلَّهُمْ فَأُولَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Itumo:" Olohun ko ko fun yin nipa awon eniti won ko ba yin jagun nipa esin, ti won ko si le yin jade kuro ninu ile yin pe ki e se rere ati deedee si won, dajudaju Olohun feran awon oluse deedee." Suratu Mumtahinah:8.
Amo awon eniti won ba mu esin ni ota, awon eleyi ni idajo tiwon ati ajosepo tiwon loto. Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" إِنَّمَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ قَاتَلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَأَخْرَجُوكُمْ مِنْ دِيَارِكُمْ وَظَاهَرُوا عَلَى إِخْرَاجِكُمْ أَنْ تَوَلَّوْهُمْ وَمَنْ يَتَوَلَّهُمْ فَأُولَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Itumo:" Amo oun ti Olohun nko fun yin nipe ki e ma mu won ni ore imule awon eniti won ngbe ogun ja yin nipa esin, ti won si le yin jade kuro ninu ile yin, ti won si nse atileyin (fun awon ota) lati le yin jade, eniti o ba mu won ni ore imule, awon wonyi ni alabosi." Suratu Mumtahinah:9.
Koda Islamu boju wo oun ti o ju eleyi lo, pelu pe o se iforo jomitoro oro lori oro esin ni eto, o si pa ase lilo awon eko iforo jomitoro oro pelu elomiran, paapaa julo pelu eniti o yapa si ni ni adisokan nigbati o ba sepe erongba pelu re ni riri ati mimo ododo. Olohun so bayi pe:
" وَلَا تُجَادِلُوا أَهْلَ الْكِتَابِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ "
Itumo:"… E ma se ma ba awon eniti A fun ni tira se ifanfa ayafi pelu daradara.." Suratu Ankaabut:46.
Olohun so lati enu Annabi Re Muhammad-ki ike ati ola Olohun ma ba- ni Eniti npe awon elesin miran bayi pe:
" قُلْ أَرَأَيْتُمْ مَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ ائْتُونِي بِكِتَابٍ مِنْ قَبْلِ هَذَا أَوْ أَثَارَةٍ مِنْ عِلْمٍ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Itumo:" Sope: eyin o wa ri oun ti e nkepe leyin Olohun? E fi han mi ohun ti won da ni ori-ile, tabi ipa kan nbe ti won ko ninu dida sanma? E mu tira kan ti o siwaju eyi wa, tabi aseku imo kan ti eyin ba je olododo." Suratu Ahkof:4.
Ki a wa fi oro okan ninu awon elesin kirisiteni ti won je oyinbo ti oruko re nje (Sir Thomas Arnold) jeri ninu iwe re ti nje (Ipepe losi inu Islam) ni oju ewe kejidinlaadota (48) nigbati o sope: o rorun ki a se idajo pe ajosepo ife ti o waye laarin omo leyin kirisiti ati awon musulumi larubawa ki i se pelu lilo agbara lati yi awon eniyan pada losi inu esin Islamu. Koda Muhammad fun ra re ti gba adehun pelu apakan awon idile kirisiteni, ti o si se adehun pe oun yoo maa so won, o si tun fun won ni ominira imaa se esin won, gegebi o se yonda fun awon alufa soosi pe ki won maa lo awon eto won ati awon idajo won ti atijo ninu ifokanbale.

Iruju eleketa:
O nbe nibi lilo awon ijiya oni-ala ti Islamu gbe kale, ijeni-nipa ati ikoja ala lori eto omoniyan.
Esi si iruju:
Ni ibere, o dara ki a se alaye pe ese ati ilufin ninu islamu pin si ona meji;
1. Ilufin ti o ni ijiya pato ti sharia gbe kale le lori. Awon ese yi ni; ipaniyan, agbere, ole jija, oti mimu, dida adapa iro moni, igbogun ti ijoba, ifesin sile.
2. Ilufin ti sharia ko gbe ijiya ti o ni odiwon kan pato kale lori, sugbon ti o fi igbe ijiya kale le lori ati sise odiwon re ti si odo awon adari ni ibamu si oun ti won ba ri pe yoo se anfani julo, eleyi ni a mo si "Ta'zeeru" (ifanileti)
Ki o di mimo fun wa pe ilufin ti o ni ijiya ti o ni odiwon ti sharia gbekale fun pin si meji:
* Ipin akooko: Awon ijiya fun ilufin ti o niise pelu awon eto omoniyan ni adayanri. Awon eto wonyi ni ipaniyan, fifi suta kan eniyan, tabi lile eniyan ni oko pansaga (sina). Oseese ki awon ijiya kan gba ki a de owo lori re nigbati eniti o ni eto ba de owo nibi eto re, ti ijiya naa yoo si pada di ijiya ti o kere (ta'ziru) ti oludari yoo fi lele fun idapada eto awujo.
Ipin elekeji: Ijiya fun awon ilufin ti o niise pelu eto Olohun, gegebi oti mimu, agbere sise, ati ole jija). Awon ijiya ilufin yi ki i gba gbigbe kuro lori eniti o ba to si, nigba ti o ba ti de odo adajo. Sugbon ti eniti o ni eto yi ba yonda re siwaju ki o to de odo adajo, bibo asiri iru re je oun ti sharia fe, paapaa julo ti eni naa ba je eniti ko gbajumo pelu iwa ibaje tele.
Ki awon apakan itonisona yi je itosona fun wa lori awon oro wa nipa lilo awon ijiya oni-ala ofin sharia:
1. Dajudaju awon ijiya oni-ala yi ninu sharia ko le je lilo ayafi lori eniti o ti balaga ti o si ni lakaye.
2. Dajudaju ijiya oni-ala wonyi ko ni maa je lilo nigbati a ba ri iruju ti o fese rinle ninu sharia. Won ti gba wa lati odo ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ti o so bayi pe: e ti ijiya kuro fun musulumi bi e ba se ni agbara mo, ti e ba ri ona abayo fun musulumi ki e ya tu u sile, dajudaju ki oludari se asise nibi sise amojukuro loore ju ki o se asise nibi ijiya lo." Hadithu yi le.
3. Dajudaju awon ijiya oni-ala yi ko le je lilo ayafi nigbati a ba ri ikoja-ala nibi awon oun pataki marun ti sharia wa lati se amojuto won (esin, emi, lakai, owo, ati molebi).
4. Awon ijiya wonyi yoo maa waye pelu sise ifirinle eniti o da ese, o si rorun ki o pada nibi afirinle re, abi ki okunrin ti o je onideede jeri lori re. Won kii gba eri obinrin nibi ijiya oni-ala.
5. Dajudaju erogba pelu ijiya ninu islamu ni ideru ba omoniyan kuro nibi gbogbo ise, tabi oro ti o ba le mu aburu wa fun awujo, tabi oun ti o ba je ikoja-ala lori eto awon ara awujo. O da gegebi odi iso fun sise amojuto awon eto yi, pelu eleyi yoo je iso fun ifokanbale awujo. Lilo ijiya yi je isemi rere fun awon eniyan. Ododo ni oro Olohun nigbati o so bayi pe:
" وَلَكُمْ فِي الْقِصَاصِ حَيَاةٌ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ
Itumo: " Isemi nbe fun ninu igbesan eyin ti e je oni-lakaye.. " Suratu Bakorah:179.
Islamu pelu se ikilo ati iderubani pelu ijiya orun ti o nbe fun eniti o ba ngbero lati lu ofin Olohun, pelu ki o fi owo dengbere mu u nibi fifi iya je eniti o ba koja ala nibi awon ase re. Nitoripe o nbe ninu omoniyan ti nkankan ko le se ni atunse re ayafi ilekoko ati agbara, lati kodi ati deru baa kuro nibi imaa lu ofin eleyi ti o le ko aburu ba awujo re. Eleyi ntoka si pipe esin islam. Nitori eleyi ni o fi jepe islamu se agbekale ijiya ti o se deedee pelu gbogbo ese kookan. O se agbekale igbesan fun ese ipaniyan, Olohun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِصَاصُ فِي الْقَتْلَى "
Itumo: " Eyin ti e Gbagbo; A pa igbesan lase fun yin nibi ipaniyan.. " Suratu Bakorah:178. Ayafi ti awon ara-ile eniti won pa ba se amojukuro nibe, nitori oro Olohun ti o so bayi pe:
" فَمَنْ عُفِيَ لَهُ مِنْ أَخِيهِ شَيْءٌ فَاتِّبَاعٌ بِالْمَعْرُوفِ وَأَدَاءٌ إِلَيْهِ بِإِحْسَانٍ "
Itumo: "..Eniti won ba se idarijin fun lati odo omo-iya re (ti won pa eniyan re), nigbana titele ofin (sisanwo eje lo kan) gegebi eto owo ti a o san fun un pelu daradara.." Suratu Bakorah:178.
O si se agbekale owo emi pelu itanran fun ese ipaniyan pelu asise, Olohun ti ola re ga julo so bayi pe:
" وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ أَنْ يَقْتُلَ مُؤْمِنًا إِلَّا خَطَأً وَمَنْ قَتَلَ مُؤْمِنًا خَطَأً فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ وَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَى أَهْلِهِ إِلَّا أَنْ يَصَّدَّقُوا فَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ عَدُوٍّ لَكُمْ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ وَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ فَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَى أَهْلِهِ وَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ شَهْرَيْنِ مُتَتَابِعَيْنِ تَوْبَةً مِنَ اللَّهِ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Itumo:" Ko to si olugbagbo ododo kan ki o pa olugbagbo ododo ayafi ti o ba seesi; eniti o ba pa onigbagbo ododo kan ni ti asise, ki o so eru kan ti o je olugbagbo ododo di omoluabi, ati ki o san owo emi fun awon ara-ile oku na, ayafi ti won ba fi toro fun u….." Suratu Nisai:92.
O si se ijiya gige lowo fun ole, Olohun so bayi pe:
" وَالسَّارِقُ وَالسَّارِقَةُ فَاقْطَعُوا أَيْدِيَهُمَا جَزَاءً بِمَا كَسَبَا نَكَالًا مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Itumo:" Ole okunrin ati ole obinrin e ge owo awon mejeji ni esan fun oun ti awon mejeji se ni ise, arikogbon lati odo Olohun, Olohun ni Alagbara Ologbon." Suratu Maidah :38.
Sugbon Islamu kii ge owo ayafi pelu awon mojemu ati onde wonyi;
1. Ko gbodo ma to odiwon owo ti sharia gbekale pe a le ge owo le lori.
2. Owo ti won ji gbodo wa ni aaye ifipamo, gegebi inu-le, tabi yara ifinkan pamo si, ki won si gba eniti o ji mu ni ita aaye naa pelu oun ti o ji. Ti won ba gbamu ninu yara ifinkan pamo si, ko leto ki won ge lowo.
3. A ko ni ge owo eniti o ba je jegudujera nibi owo ti o je oluso le lori, gegebi osise ile ise ifowopamo ti o nmu ninu owo ilese eyi ti o ti n sise, nitoripe mimu owo ile-se yi waye latari sise aseeto eni ti o ni ile ise, tabi adari ile ise, nitoripe o je dandan lori adari lati se eto gbogbo irinse ti yoo kodi iru awon isele wonyi.
4. A ko ni ge owo eniti o gba ile lowo eniti o ni i, gegebi ki o gba ile pelu agbara, ti yoo wa maa sope: emi ni mo nile yi, nitoripe eniti o ni ile lododo ni anfaani ki o pe awon eniyan, tabi olopa lati ba le awon eniti o je gaba le eto re lori, ati lati gba eto re fun.
5. A ko ni ge owo ole ti iruju nbe nibi ole jija re, gegebi ki o sepe oun ti o fa jijale re ni ebi, ti awon oun ti o ji si je awon oun ti o je laluri ti aisi re si le fa iparun fun.
Ese ole jija je okan ninu awon ese ti oni ewu ti o ma nfa aburu fun awujo, ti o si ma nderu ba awon ara ilu nibi owo, dukia, ati emi won, ti yoo si ma se idiwo fun ifokanbale ati isinmi eleyi ti islamu nfe lati pese fun awon ara awujo. Nitoripe ti ole ba ri eniti o fe di i lowo nibi ole jija re, ko ko lati pa erufe eni be ti o fe di i lowo, gegebi o ti seese ki o koja ala nibi dukia awon eniyan. Irufe ese bayi ni bukata si ijiya nla ti yoo kodi re, ti yoo si wu tigbongbo tigbongbo. Ti ole ba mo pe won yoo ge owo oun, yoo jawo nibi ole jija, yoo si so owo re kuro nibi gige, owo awon eniyan naa yoo si la kuro nibi jiji.
O se igbekale ijiya oni-ala ibanijagun lori awon eniti won ba nda awon eniyan lona ti won si nderu ba won leyin ti won ti ni ifokanbale pelu awon nkan ija oloro, nitori oro Olohun ti o so bayi pe:
" إِنَّمَا جَزَاءُ الَّذِينَ يُحَارِبُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَسْعَوْنَ فِي الْأَرْضِ فَسَادًا أَنْ يُقَتَّلُوا أَوْ يُصَلَّبُوا أَوْ تُقَطَّعَ أَيْدِيهِمْ وَأَرْجُلُهُمْ مِنْ خِلَافٍ أَوْ يُنْفَوْا مِنَ الْأَرْضِ ذَلِكَ لَهُمْ خِزْيٌ فِي الدُّنْيَا وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ * إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا مِنْ قَبْلِ أَنْ تَقْدِرُوا عَلَيْهِمْ فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Itumo:" Dajudaju esan awon eniti nja Olohun logun ati ojise Re ti won si nse ibaje ni ori ile ni pe ki won pa won, tabi ki won fi won se alore, tabi ki won ge won ni owo ati ese ni ipasi-payo, tabi ki won le won jade kuro ni ilu. Eyi je itiju fun won ni aye, iya ti o tobi si nbe fun won ni orun. * Ayafi awon ti won ba ronupiwada ki agbara yin to ka won, nitorina ki e mo daju pe Olohun ni Alaforijin Onike" Suratu Maidah:33-34.
A o ma se idiyaje ni ibamu si bi ese ba ti ri. Lati odo omo Abass-ki Olohun ki O yonu si - o sope: Aaya yi sokale lori eniti o gbe ogun ja Olohun ati ojise Re, dajudaju esan eniti o ba ja Olohun ati ojise Re logun ti o koja ala, ti o dana, ti o si pa enia, ti o si tun gba dukia re, won yoo se e ni alore. Ti o ba pa enia sugbon ti ko gba dukia re, won yoo pa. Ti o ba gba dukia, sugbon ti ko pa enia, won yoo ge owo re ni ipasi-payo. Ti o ba sa lo ti won ko gbamu, iyen ni lile jade kuro ni ilu. Bayhaqi ati Daraqtni ni won gba wa.
O se agbekale ijiya egba nina lori eniti o ba le oko ibaje mo omuluwabi elomiran. Olohun so bayi pe:
" وَالَّذِينَ يَرْمُونَ الْمُحْصَنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَأْتُوا بِأَرْبَعَةِ شُهَدَاءَ فَاجْلِدُوهُمْ ثَمَانِينَ جَلْدَةً وَلَا تَقْبَلُوا لَهُمْ شَهَادَةً أَبَدًا وَأُولَئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ (4) "
Itumo:" Awon eniti won ba pe pansaga mo awon obinrin ti won ki i se oni pansaga, leyina ti won kori eleri merin mu wa, e na won ni ogorin egba…" Suratu Nur:4.
Erongba Islam lori lilo ijiya oni-ala yi ni lati so omoluwabi awon eniyan, ati iso won kuro nibi ki won fi abuku kan an, ati lati so enu kuro nibi ki o ma so oun ti o ba fe, pelu fi fi esun kan awon enia laini idi kan ti o fi ese mu le. Ninu oun ti ko pamo ni pe suta yoo ba emi nibi fi fi esun kan omoniyan, nitori oun ti yoo ba latara oro ti awon eniyan yoo maa so nipa re ti ko si nife si. Toripe omoluabi eniyan ninu islamu ni ipo nla, gegebi o se je pe ima soro nipa re je oun ti o le fa ota ati ibinu si ara eni laarin awon ara awujo, eleyi ti o si le se okunfa awon iwa ti o lewu, gegebi ipaniyan.
Nitori eleyi ni ofin sharia fi gbe ijiya ti yoo kodi isesi yi kale, nipa pe ki won je eniti o ba le oko ibaje mo elomiran ni ijiya ti o ye, nigbati o jepe oun ti o so ko fidi mule. Eleyi yoo je iso fun awon eto kuro nibi iyepere. Eleyi je ogidi deedee ati amojuto ododo lori awon eto omoniyan. Islamu ko fi mo lori agbekale ijiya-oni ala nikan, eleyi ti nse ijiya-ara, bi kosepe o tun se agbekale ijiya-emi lori eniti o ba le oko aburu mo elomiran ki o le to iya aburu re wo, pelu pe won ko gbodo gba irufe eni bee ni olododo mo, won ko si gbodo gba ijeri re mo, yoo si tun gba iroyin poki ayafi ti o ba ronupiwada ni ironupiwada tooto.
Gbogbo eleyi ko je nkankan ju isojukokoro islamu lori ati so awon eto omoniyan kuro nibi sise ibaje ati aburu pelu re, yala pelu ise abi oro. Olohun so bayi pe:
" وَالَّذِينَ يَرْمُونَ الْمُحْصَنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَأْتُوا بِأَرْبَعَةِ شُهَدَاءَ فَاجْلِدُوهُمْ ثَمَانِينَ جَلْدَةً وَلَا تَقْبَلُوا لَهُمْ شَهَادَةً أَبَدًا وَأُولَئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ * إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا مِنْ بَعْدِ ذَلِكَ وَأَصْلَحُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Itumo:" Awon ti won npe pansaga mo awon obinrin ti won kii se oni pansaga, leyina ti won ko ri eleri merin mu wa, e na won ni ogorin egba, e ko si gbodo gba eri won lailai, awon eleyi ni poki. * Ayafi awon eniti won ba ronupiwada leyin eyi, ti won si se rere, dajudaju Olohun ni Alaforijin Olukeni." Suratu Nur: 4-5.
O si se agbekale nina ni legba fun ese sise agbere fun eni ti ko tii se igbeyawo, gegebi ki won fi esun sina kan odo lokunrin pe o ba odo lobirin se asepo lai leto. Olohun so bayi pe:
" الزَّانِيَةُ وَالزَّانِي فَاجْلِدُوا كُلَّ وَاحِدٍ مِنْهُمَا مِائَةَ جَلْدَةٍ "
Itumo:" Pansaga obinrin ati pansaga okunrin e na enikookan ninu awon mejeji ni ogorun egba…" Suratu Nur:2.
Sugbon ti esun sise pansaga (sina) ba da lori awon eniti won ti se igbeyawo, eto awon wonyi ni ki won le won ni oko pa, eleyi ki i se ninu islamu nikan, bikosepe o wa ninu gbogbo ofin sama ti o ti rekoja (yahudi ati Nasara). Ofin yi (lileni loko pa) ko ni maa je lilo ayafi pelu awon mojemu kan ti o ni agbara ti ko rorun lati ri. Won ko ni le alagbere lokunrin tabi lobirin ni oko ayafi ni awon aye meji yi;
* Aye akoko: Ki awon mejeji se afirinle pe awon jo se asepo ni ifirinle ti ko ni ijeni nipa ninu, gegebi o ti je pe won ko ni se idajo yi lori won ni akoko ifirinle awon mejeji ayafi leyin ipaara ifirinle yi ni eemerin ni aye otooto merin ti o yato si ara won. Bakan naa won gbodo ba won so awon oro ti o le kodi won nibi sise afirinle oro wonyi, gegebi ki won so fun pe; boya e kan di mo ara yin ni, tabi e kan fi enu kan ara yin, tabi e kan lo mo ara yin nii, nitori ki won le fun won ni anfaani ati seri kuro nibi esun ti won fi kan ara won.
 Lati odo omo Abass-ki Olohun yonu si awon mejeji- sope: nigbati Maaizu omo Malik wa si odo ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- (pe oun se pansaga), Ojise Olohun sope: abi o kan fi enu ko lenu? abi o kan di mo lasan? abi o kan woo la san? o sope: kori be, ire ojise Olohun! Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) bi leere pe: nje o ba ni asepo ni asepo loko laya ni bi? o si dahun wipe beeni, nigbana ni Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- pa ase pe ki won le loko." Sahih Al-Bukhari.
Ti won ko ba seri pada kuro nibi esun sina ti won fi kan ara won, sugbon ni asiko ti won nle won ni oko lowo won wa salo, won yoo ka eleyi si pe won ti seri pada nibi oro won, won yoo si da lilo ijiya yi duro fun won. Lati odo baba Huraerah-ki Olohun yonu si- o sope: Maaizu Al-Aslami wa si odo ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- o ba sope: mo se sina, Ojise Olohun gbe oju kuro lodo re, leyinaa o tun bo siwaju Ojise Olohun ni egbe keji, o ba tun sope: ani mo se sina, Ojise Olohun tun gbe oju kuro lodo re, titi o fi se bee ni eemerin, nigbayi Ojise Olohun wa pa ase ki won le ni oko. Sugbon nigbati o ri inira oko o salo, (ni won ba le pelu oko), leyina won fi isele yi to ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- leti. O ba sope: e ba ti fii sile." Sahih Ibn Hibban.
* Aaye elekeji: Ki awon eniyan merin ti won je olododo jeri le awon mejeji lori pe awon ri won po lori ara won ni riri ti o daju pe won nse asepo ni (pelu riri enu asakari okunrin ninu abe obirin).
Be na si nipe won ko ni lo ofin ijiya yi le won lori nigbati iruju ba wa, gegebi pe won di mo ara won, abi won nfi enu ko ara won.
Ki o di mimo pe ese sina kii se alamori kan ti o niise pelu onisina lokunrn ati onisina lobirin nikan, bi kii sepe o je ikoja ala lori eto awujo, ati awon ara inu re. Awon ese ti o sopo mo sina po, ninu re ni;
1. Fifonka awon iwa ibaje, eleyi ti yoo maa se okunfa opolopo awon arun kogboogun orisirisi laarin awujo, pelu aburu re ti yoo de odo eni ti ko da ese. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe: Eyin Muhajirina! Nkan marun wa ti o ba sele si yin, atipe mo nwa Olohun niso kuro nibi ki o sele si yin. Sina (pansaga) ko ni di oun ti o fonka ni awujo kan ayafi ki ajakale arun ati ilekoko sele si won, eyiti ko sele si awon ti siwaju won. Won ko ni maa din osuwon ku ayafi ki iyan gba won mu ati ki won yan oludari alabosi le won lori. Won ko ni ko lati yo zakah, ayafi ki ojo ma ro fun won lati sama, ti ko ba se nitori awon eran-osin, ojo o ba ma ro fun won. Won ko ni yapa adehun Olohun ati ti ojise Re, ayafi ki Olohun je ki ota ti kii se ara won je gaba le won lori, won yoo si gba die ninu oun ti nbe lowo won. Awon eni ti awon olori won ko ba maa se idajo pelu iwe Olohun, ti won ki wa rere ninu oun ti Olohun so kale ayafi ki Olohun fi won se pasan fun ara won. Sahih Ibn Majah.
2. Darudapo awon molebi mo ara won ninu awujo, yoo maa se okunfa ki omo ki o ma mo baba re, tabi iya re, o tun seese ki won se afiti omo si odo eniti kii se obi re, eleyi ti yoo maa kodi sise afiti re si odo molebi re, ti yoo si maa dena eleto nibi eto re, pelu pe ki won fun eniti ko leto si ogun ni ogun, ati ki won kodi eniti oni eto si ogun kuro nibi eto re. Bakan naa sise igbeyawo pelu eniti ko ni eto.
3. Mi maa be awon omo ti won ko ni ese lorun ni awujo, ni eniti won ko ni ni anfani si aanu ati itoju iya ati baba, ti won ko tun ni ni molebi ti won yoo se afiti won si, ti eleyi si le se okunfa awon aisan opolo ti o lewu, ti o le fa ki won maa wu iwa aburu, ti yoo si ni ilapa aburu lori awujo latara mi maa be awon eniyan ti won ngbero aida si awon ara awujo. Iya ati baba da gegebi ilu fun awon omo ti won yoo maa seri lo si odo re, ti won yoo maa go si abe iboji re, ti won yoo si maa gbadun pelu ifokanbale ati alafia ninu re.
O se agbekale ijiya nina fun ese oti mimu, ati gbogbo oun ti o dabi oti ninu awon oun ti mo nfa ihunrira.
Omoniyan ninu Islamu ni ominira jije ati mimu oun ti o ba wu u, ayafi awon ipin ounje kan ti won se ni eewo fun un, gegebi eran okunbete, eje, eran elede, ati ohun ti won ba pa fun elomiran leyin Olohun. Awon eleyi ko ni ijiya kan pato ninu ofin sharia, bikosepe o je dandan fun eniti o ba se won ki o ronupiwada losi odo Olohun. Sugbon eniti ba nse afihan sise re lai bikita, won yoo jee ni iya ifani leti (ta'ziru) ti oludari yoo se agbekale re ni ibamu si anfani gbogbogbo.
Bakanna nipe omoniyan ni ominira nibi oun mimu, ayafi awon oun ti a se ni eewo fun ki o ma ba se ni aburu. Aburu oti mimu ko mo lori eniti o mu nikan, bikosepe aburu re tataporo de ori awujo, nitori eleyi ni won fi npe oti ni iya awon oun ti ko dara, oun naa si lo fa ti won fi gbe ijiya nina kale le lori lati kodi re ni awujo. Nitoripe islamu nwa lati se amojuto lakaye, ati igbonmo omoniyan kuro nibi gbogbo oun ti o ba le ko ipalara ba, ti o si le se akoba fun ise re, nitoripe o fe omoniyan ti ko ni kuro ni ipo omoniyan losi ipo awon eda miran ti won ko ni lakaye ati oye. Ninu awon aburu ti o wa nibi oti mimu ni;
1. Eniti o ba je omuti o seese ki o pa eniyan, ki o se sina pelu eleewo re latara ihunrira oti. Lati odo Uthman omo Affan- ki Olohun yonu si- o sope: e jina si iya aburu (ti se oti) toripe arakunrin kan ninu awon ti o siwaju yin je eniti ma nse ijosin ti si ma njina si awon eniyan, ni emi arabirin kan ba fa si, ni o ba ran omo-odo kan sii, ni eni ti nsope: a fee fiyin jeri nkankan, ni arakunrin yi ba wo le ti arabirin naa, ni kete ti o wole ni arabirin yi ba ti ile kun mo o, bayi ni o ri arabirin kan ti o joko ti o si rewa pupo,ti omode kunrin kan ati ife koobu ti oti wa ninu re si wa ni egbe re, ni arabinrin yi ba sope: a wa ko pe o fun ijeri kankan, sugbon mo pe o ki o le pa arakunrin yi, abi ki o ba mi ni asepo, abi ki o mu ife koobu kan ninu oti yi, ti o ba ko lai se be e, maa pariwo re sita, maa si fi o se esin. Nigbati arakunrin yi ri wipe ko si ona abayo fun oun, o sope: fun mi ni koobu oti mu, ni o ba fun ni oti, o tun sope: fun mi si i, koye-kogbo ni eniti nbeere alekun oti titi ti o fi se asepo pelu arabinrin naa, ti o si pa omo naa, e jina si oti, dajudaju mo fi Olohun nbura pe: igbagbo ati oti mimu ko le papo ninu igbaya okunrin kan soso, okan ninu won yoo jade fun ekeji."
2. Didunimo oti mimu ati nkan oloro yoo so omoniyan di ole alailagbara, ti yoo si di eru lori awujo re, ti yoo wa ma wa gbogbo ona lati ri oti mu, tabi owo ti yoo fi ra a, tabi ki o ta nkan ini re, tabi ki o ji i nitori ati mu oti.
3. Awon aburu ilera-ara ti o lewu ni nbe nibi mimu oti. Imo eko itoju ara ode-oni fi eleyi rinle nipa pe o ma nba edo je ati nkan miran ninu ara.
4. Ina ina-apa ati fifi asiko sofo lai si anfaani kan ti yoo ri nibe, koda aburu ti o han ni o wa nibe fun gbogbo oni-lakaye.
5. Sise leewo fun awujo sise anfaani pelu agbara ati lakaye awon ara-ilu, ti eleyi si je ikojala lori eto awujo.
6. Yoo mu iyi ati pelepele kuro loju eniti ba n mu u, nitoripe o maa nje ki omoniyan wa ni ipo eyin ti ko si ni ni itiju, koda o le so da gegebi eranko, ti eleyi si je oun ti islamu ko fe fun omoniyan.
Leyina, Islamu gbe opo apapo kan kale ti o gbe gbogbo ijiya le lori. Olohun so bayi pe:
" وَجَزَاءُ سَيِّئَةٍ سَيِّئَةٌ مِثْلُهَا "
Itumo: " .. Atipe esan aburu ni aburu bi tire .." Suratu Shura:40.
Ati oro Re ti o so bayi pe:
" وَإِنْ عَاقَبْتُمْ فَعَاقِبُوا بِمِثْلِ مَا عُوقِبْتُمْ بِهِ "
Itumo:" Ti e ba fe gba esan, ki e gba esan ni iru iya ti won fi je yin .. " Suratu Nahl: 126.
Ko di oun mimo pe dajudaju islamu ko se lilo awon ijiya yi ni oranyan dandan gbon, bi kii sepe o fi ona sise amojukuro sile ti eniti o ni iwo ba ti gba bee, nitori oro Olohun ti o so bayi pe:
" وَلْيَعْفُوا وَلْيَصْفَحُوا "
Itumo: "… ki won si se amojukuro (fun won), ki won si ma se fi iya je won .. " Suratu Nur:22.
Ati oro Olohun ti o so bayi pe:
" فَمَنْ عَفَا وَأَصْلَحَ فَأَجْرُهُ عَلَى اللَّهِ "
Itumo: " .. Enikeni ti o ba se amojukuro ti o si se atunse, esan re nbe ni odo Olohun…"
Dajudaju islamu ko gbero esan gbigba ati ibaje pelu sise agbekale lilo awon ijiya yi, bikosepe o gbero lati so awon eto omoniyan latara awon idiyaje wonyi ati lati gbin ifokanbale ati alafia si inu awujo, ati lati kodi eniti o ngbero ibaje pelu alaafia ati ifokanbale awujo, ati lati fo awujo mo kuro nibi iwa ese. Ti apaniyan ba mo pe won yoo pa oun naa, ti ole si mo pe won yoo ge oun lowo, ti onipansaga si mo pe won yoo na oun ni egba, ti olu le oko ibaje mo elomiran si mo pe won yoo na oun ni egba, won yoo jawo kuro nibi oun ti won gbero re, bayi ni yoo la emi re ati ti elomiran. Ododo ni oro Olohun ti O sope:
" وَلَكُمْ فِي الْقِصَاصِ حَيَاةٌ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ
Itumo: " Isemi nbe fun yin nibi esan gbigba eyin ti oni lakaye .. " Suratu Bakorah:179.
O seese ki olusoro kan sope: awon ijiya ti sharia se agbekale re fun apakan awon ese je ijiya ti o le koko. Won yoo so fun un pe: gbogbo wa ni a gba pe ese ni won, ti won si ni aburu ti ko pamo lori awujo, atipe dajudaju o pan dandan ki a kodi re, ki a si ko o, ki a si gbe ijiya kale le lori. Ki a bi ara wa leere, ki a si woye si; nje awon ijiya ti sharia gbekale ni oni oore ti o si se anfani julo nibi kiko ibaje ati sise adinku re ni, tabi awon ijiya ti omoniyan gbe kale?
Awon ijiya ti Islamu gbe kale o seese ki ole koko fun eni ti ba nwo lasan, sugbon o je ijiya tooto, ti o si ba gbogbo asiko ati lakaye mu fun eni ti o ba ronu si daada. Nitoripe o je itosona pelu iyonda Olohun fun ati dena ese. Nitoripe eni ti lakaye pe yoo pa ase fun alufin pe ki o da eto awon ti o fi aburu kan pada siwaju ki o to se pele pelu re. Nigbana, o je dandan ki a kodi alaburu nitori ati de se idaabobo eyi ti yoo je iso fun gbogbo awujo.
Dajudaju awon eniti won gba alaye nipa ijiya ninu Islamu lodo awon eniyan ti won je oni-keeta esin islamu, yala ninu awon ti won npe ara won mo islamu ni, tabi ninu awon ota re, ti won si nlero pe awujo islamu je awujo eru-jeje ati ita eje sile, awon ara inu re si je alaisan, ti eleyi yoo je eniti won ge lowo, eleyi yoo je eniti won le loko, ti eleyi yoo si je eniti won na legba. Won lero pe lilo ijiya-oni-ala yi je oun ti ma nwaye ni ojojumo gegebi won ti se ma nlo awon ofin ati idajo won ti o niise pelu ajosepo ara-ilu. O to ki a se itoka si itan islamu pe a ko ri eniti won le loko pa ju eniyan meji tabi meta lo, ni awon eniti won da ese ti won si fa ara won sile fun idajo Olohun, ki o le afomo fun won kuro nibi ese.

Iruju eleketa:
Dajudaju lilo idajo ijiya fun eni ti o ko esin (Islam) sile je ikoja-ala lori eto ominira omoniyan eleyi ti esin Islam se afinrinle re, bakan naa o tun tako oro Olohun ti o sope:
" لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ "
Itumo:" Ko si ijeni nipa ninu islam .." Suratu Bakorah:256.
Esi si iruju yi:
Ofin sharia islam se agbekale pipa fun ese yiyipada si keferi, nitori oro ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ti o sope:" Eniti o ba paro esin re (ti o di keferi) e pa." Al-Bukhari.
Nibi yi o ye ki a se akiyesi nkan pataki meji, awon ni wonyi;
1. Dajudaju ijiya pipa wa fun eniti kikoomo re ba han sita, ti o si npepe si ki awon eniyan tako eko ati ofin islamu, ti o si ngba won ni iyanju lori re, nitoripe ikoomo re yi da gegebi ijade eni ti o mo nipa Islam si ofin Sharia. Sugbon ti o ba sepe ikoomo re ko fi han si awon eniyan, idajo eleyi di odo Olohun, nitoripe Islamu ma nse idajo lori awon oun ti o ba han sita, sugbon awon oun ti o pamo, ko si eniti o moo ayafi Olohun.
2. Won yoo gba ni imoran pe ki o ronupiwada laarin ojo meta. Awon agbalagba aafa yoo gba ni iyanju lori eleyi, ti o ba seri pada kuro nibi ikoomo re, eleyi ni oun ti Islamu nfe, sugbon ti o ba ko, won yoo paa nitori ati dena aburu re, ati lati so awujo kuro nibi ewu re.
Kikoomo je ifi esin ati eko re se awewa, eleyi ti ofin islamu ko nife si, koda eleyi le koko ju keferi ipile lo. Olohun so bayi pe:
" إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا ثُمَّ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا ثُمَّ ازْدَادُوا كُفْرًا لَمْ يَكُنِ اللَّهُ لِيَغْفِرَ لَهُمْ وَلَا لِيَهْدِيَهُمْ سَبِيلًا
Itumo;" Dajudaju awon eniti won gbagbo, leyinna won se aigbagbo, leyinna won (tun) gbagbo, leyinna won tun se aigbagbo, leyinna won se alekun ninu aigbagbo, Olohun ko ni se aforijin fun won, ko si ni to won si oju-ona (ti oto).
Ki lode ti won yoo fi pa eniti-okoomo?
1. Kikoomo je ipepe ti oni ewu eyiti eniti-okoomo gbe dide si Islamu ti yoo si ko aburu ba awon musulumi, ti yoo si tun ko fun elomiran lati gba islamu. Isesi yi da gegebi enipe o so pe: mo wo inu esin islamu, mo si gbee wo, sugbon ko si oore ninu re, tabi pe esin re tele ni oore ju Islamu lo. Eleyi je okunfa kan lati da esin islamu wo, eleyi ti awon ota re ma nlo. Won yoo wo inu esin islamu, leyinna won yoo jade pada. Ni atijo opolopo awon yahudi ni won gba islamu ni erogba ati wo igbagbo awon musulumi ninu esin won, ati lati kodi elomiran nibi wiwo inu islamu. Olohun ti so bayi pe:
" وقَالَتْ طَائِفَةٌ مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ آمِنُوا بِالَّذِي أُنْزِلَ عَلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَجْهَ النَّهَارِ وَاكْفُرُوا آخِرَهُ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Itumo:" Apakan ninu awon oni-tira si wipe: e gba oun ti won sokale fun awon onigbagbo gbo ni ibere ojo, ki e si se aigbogbo si ni igbehin re, ki won le ba seri pada." Suratu Ahl-Imran:72.
2. Dajudaju islamu nfe lodo eniti o ba fe gba Islamu pe ki o wo inu re tokan tokan pelu aniyan ti o dara, ati leyin iwadi ti o yanranti, ti o wa gba lati wo inu re leyin eyi, iru eleyi ni oun ti Islamu nfe. Ko leto lati wo inu islamu pelu aniyan lati jade kuro nibe pada nitori ati ko royiroyi ba igbagbo awon musulumi, ati lati ko fun elomiran ninu awon ti kii se musulumi lati wo inu Islamu ninu awon ti njeran lati wo inu re.
3. Islamu ri kikoomo si nkan ti ko mo lori eniti okoomo nikan, koda ko sepe eleyi ti ko han sita, nitoripe kikoomo kuro ninu Islamu kii se ayipada odisokan eniti okoomo nikan, bikosepe pelu kikoomo re, o jade tako ofin, ijade re yi si ni yoo je okunfa ibaje si ofin yi, eleyi ti yoo ko aburu ba gbogbo awujo. Eleyi si je ohun ti Islamu ko fe.
Eleyi gegebi o se wa ninu Islamu naa ni o wa ninu awon ofin miran ti o sepe eniti o ba yapa si ofin, ti si ngbero lati yi pada, ati lati da darudapo sile sinu re, won yoo lo awon ijiya ti o seese ki o buru ju pipa lo le irufe eni bee lori ni asiko ti a wa yi, gegebi idiya je emi, abi ara ti yio pada de ipo pipa, abi ki won le won jade kuro ninu ilu, pelu gbigba dukia won, abi ki won ta eje re sile, ti won yoo si fi iya jee ni oju-aye re ati leyin iku re pelu fifi oku re sesin, won yoo si fi aburu kan awon ara ile re, ati awon molebi re pelu.

Iruju eleekarun:
Dajudaju sise igbeyawo obinrin musuluma pelu eniti kii se musulumi ni eewo je itapa si eto omoniyan, nibi pe o je ikoja-ala lori ominira aladani omoniyan eleyi ti o fun ni eto lati fe eniti o ba wuu.
Esi si iruju yi:
Kiko fun musulumi lobirin lati se igbeyawo pelu eniti kii se musulumi lokunrin kii se onde fun ominira omoniyan nibi igbeyawo nitori esin, bikosepe o je amojuto fun ebi kuro nibi darudapo eleyi ti o le waye nitori iyato esin, nigbati oko ko ba gbe aponle fun awon oun owo esin iyawo ni ibamusi adisokan re (oko). Nitoripe obinrin je eka kan ninu awon eka meji ti ebi ni, ole si ni obinrin ma nje ni opolopo igba niwaju oko re, eleyi ti yoo ni ilapa lori re
Latara eleyi, awon nkan meta kan jeyo, ti won si yato si ara won nibi idajo, sugbon won jeyo lati ara nkankan soso ti ati se alaye re lo nibi oro ti o saju. Awon nkan naa niyi;
1. Alakoko: Sise igbeyawo musulumi pelu elebo lobirin, abi eniti ko gbagbo ninu Olohun, Islamu ti se eleyi ni eewo, nitoripe adisokan musulumi ko le se aponle awon oun owo iyawo yi lailai, tabi awon adisokan re. Eleyi yoo si maa fa ariyanjiyan ati ija, Islamu si ka kikora eni sile si oun ti o je eto ti Olohun ko nife si. Nitori eleyi ni Islamu ko se faaye sile fun musulumi lati fe elebo lobirin. Nigbati oro ba ri bayi, o dara ki won se irufe igbeyawo be ni eewo, eleyi ti oko ko ni gbe aponle ninu re fun awon oun owo esin iyawo ati awon adisokan re, eleyi yoo si maa fa ija laarin won.
2. Ekeji: Islamu ki okunrin musulumi se igbeyawo pelu elesin kiristeni (nasara), abi yahudi ni eto, nitoripe Islamu se afirinle iwe ti a firan Isa omo Moriyamo-ki alafia Olohun ma ba- o si gba pe ojise Olohun ni, won bi ni ona iyanu, bakanna si ni Islamu se afirinle iwe ti a firan Musa-ki alafia Olohun ma ba- o si gba pe ojise Olohun ni si awon omo isireli. Nitori eleyi ni oo fi leri iyawo kan ti o je nasara, abi yahudi ti oni akolekan lori ati duro sinsin lori esin re (gegebi o ti wa ninu tira won) ki o kuro lodo oko re ti o je musulumi, ti yoo wa fa wahala ati ija si inu ebi, nitoripe Islamu se afirinle ojise re pe o je eniti a ran lati odo Olohun. Nitori eleyi, ko si oun ti o kodi nibi sise iru igbeyawo bayi ninu Islam, koda ko sepe esin yato si ara won.
3. Eleketa: Sise igbeyawo eniti kii se musulumi gegebi kiristeni, abi yahudi ni apejuwe pelu obinrin musulumi je eewo ninu Islamu, nitoripe oko ti o je kiristeni, abi yahudi ko le ni igbagbo si oun ti a firan ojise nla Muhammadu-ki ike ati ola Olohun ma ba- bikosepe yoo tako o pelu adisokan ati oro ni oun ti yoo fa ki iyawo ti o je musulumah ko jade kuro lodo oko re, ti yoo wa fa ija ati wahala si inu ebi, nitori eleyi ni Islamu fi se irufe igbeyawo bayi ni eewo.

Iruju elekefa:
Ilana imuni leru ti o wa ninu Islamu je oun ti o tako oun ti Islam npepe si nibi dogbandogba ti o pe, eleyi ti gbogbo omoniyan ninu re yoo seri sibi ipile kan soso.
Esi si iruju yi:
Ni akoko, sise afirinle ilana imuni leru ninu Islamu je oun ti o jeyo nipase eto isuna ati awujo ti ko si ona abayo kuro ninu re, nitoripe dajudaju awujo eleyi ti Islam dide ninu re je awujo ti o gbe ara le ini eru nibi eto isuna ati eto ajosepo awujo. kii se ni awujo erekusu ile larubawa eyiti Islamu dide nibe nikan, bikosepe ni gbogbo awujo agbaye nigbana. Eleyi si je oun amulo ninu gbogbo esin ti o ti siwaju Islamu.
 Nipaapa o ti wa ninu iwe Deuteronomy ese ogun pe:" nigbati o ba sun mo ilu kan lati jaa logun, pe won si atunse, ti won ba je ipe re si atunse,ti won si tun si ilekun fun o, gbogbo awon eniyan ti nbe ninu re ma ro fun o, won yoo si je eru fun o, ti won ko ba je ipepe re, ti won si gbogun ko e, ki o se won mole, ti Olohun ba fun o ni agbara lori won, ki o pa gbogbo awon okunrin inu re pelu ida, sugbon awon obinrin ati omode, ati eran osin, ati gbogbo oun ti n be ninu ilu naa yoo di ebun fun o, o wa maa je oun-ini ota re, eleyi ti Olohun se fun o, bayi ni o se maa se pelu gbogbo ilu ti o jina si o, kii se awon ilu awon ijo yi nibiyi. sugbon awon ilu awon eniyan wonyi eleyi ti Oluwa se fun o, ma se fi nkankan sile ninu re, se ni eewo niti eewo.
Dajudaju Islamu woye si ilana ti o jina, ti o duro lori lilo ofin eleseese nibi kikodi imuni sin, gegebi o se se nibi sise oti mimu ni eewo. Ni apejuwe sise oti ni eewo ko wa ni eekan soso, bikosepe won so di eewo leyin opolopo igbese (meta).
Igbese akoko, Olohun so bayi pe:
" يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ قُلْ فِيهِمَا إِثْمٌ كَبِيرٌ وَمَنَافِعُ لِلنَّاسِ وَإِثْمُهُمَا أَكْبَرُ مِنْ نَفْعِهِمَا "
Itumo:" Won yoo bi o nipa oti (mimu) ati tete-tita, So (fun won) pe: nbe ninu awon mejeji ese ti o tobi ati oore fun omoniyan, atipe ese inu awon mejeji ju oore ti nbe ninu won lo.." Suratu Bakorah:219.
Nigbati o di pe awon eniyan bere sii gba ipepe Islamu, oro Olohun ti o lo bayi sokale pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَقْرَبُوا الصَّلَاةَ وَأَنْتُمْ سُكَارَى حَتَّى تَعْلَمُوا مَا تَقُولُونَ "
Itumo:" A pe eyin ti e gbagbo lododo e ma se sunmo irun kiki, nigbati eyin un-rira ti ti eyin yoo fi mo ohun ti e nwi.." Suratu Nisai:43.
Nigbati o di pe igbagbo ti fi ese wale ninu okan awon musulumi, ti won si bere sii gba Islamu ati won si nko eko re, ti won si nti ase Olohun ati ti ojise Re saju gbogbo nkan, sise oti di eewo ba sokale. Olohun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالْأَنْصَابُ وَالْأَزْلَامُ رِجْسٌ مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Itumo: Eyin onigbagbo ododo, dajudaju oti, ati tete-tita, ati orisa bibo, ati fifi ofa pin nkan je egbin ninu ise esu, nitorina e jina si ki e le ba jere." Suratu Maida:90.
Nipaapa Islamu se igbiyanju lati fopin si imuni leru gegebi igbiyanju re lati kodi oti-mimu, ko ko imuni-leru pelu gbigba ona oju le, sugbon o se igbiyanju kiko re pelu ona ogbon nibi mimaa koo diedie titi yoo fi di asiko kan ti yoo fi pare. O bere pelu ona ifun awon eru ni ominira nibi mimaa ri ara won si ole, ati alaini-agbara, ati imaa ri ara won si ero eyin. O se adapada aponle ati ije omoniyan fun won, o si se won gegebi omo-iya lodo awon olowo won, nitoripe imuni-leru ninu Islamu je oun ti o jawa ti kii se ipile.
Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe:" Awon omo iya (ti won wa ni oko eru yin) je eru yin ti won yoo maa ba yin mojuto nkan ini yin, eniti omo-iya re ba nbe labe ikapani re, ki o ya maa fun je ninu oun ti o nje, ki o si maa fun wo ninu oun ti o nwo, e ko si gbodo la bo won lorun oun ti o ju agbara won lo, ti e ba la bo won lorun, ki e ran won lowo." Bukhari.
O pa ase sise rere ati pelepele si awon eru nibi oro ati ise, Olohun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" وَاعْبُدُوا اللَّهَ وَلَا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا وَبِذِي الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينِ وَالْجَارِ ذِي الْقُرْبَى وَالْجَارِ الْجُنُبِ وَالصَّاحِبِ بِالْجَنْبِ وَابْنِ السَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ مَنْ كَانَ مُخْتَالًا فَخُورًا
Itumo:" E ma sin Olohun, ki e si ma da orogun pelu Re, ki e si ma se rere si awon obi yin mejeji, ati awon ibatan ti o sunmo yin, ati awon omo-orukan, ati awon alaini, ati awon aladugbo ti o sunmo yin, ati awon aladugbo ti o jina, ati ore alabarin, ati omo oju-ona, ati awon ti owo otun yin ni, dajudaju Olohun ko feran awon olugberaga onifaari." Suratu nisai:36.
Islamu se akolekan aponle won, o si ko gbogbo oun ti o le je okunfa iranti ipo ti won wa tele. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- so bayi pe:" Enikeni ninu yin ko gbodo sope: eru mi (lokunrin, tabi lobirin), ki o sope: omo mi (lokunrin, tabi lobirin). Bukhari.
Ki odi mimo fun wa pe dajudaju imuni-leru ninu Islamu je imuni-leru niti ara nikan, kii se imuni-leru lakaye ati ironu, eru ni ominira ki o wa lori esin re ati adiokan re ti o ba fe be. Islamu ti se apejuwe gegebi isesi re ni apejuwe nla nibi dogbandogba omoniyan, o si se ajulo laarin omoniyan pelu iberu Olohun nigbati o se ije omo-iya laarin won ati awon ti won ko si ni oko-eru. Koda Islamu woye si oun ti o ju eleyi lo, nipaapa ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- fi Zaynab omo Jahsh eni ti o ni ola ati ipo fun eru re Zayd, gegebi o se yan omo-odo re – Zayd- ni oludari lori iko omo-ogun ti awon olori awon saabe re wa.
Islamu lo ona meji lati fi opin si imuni-leru, ni ona ti orewa ti ko mu aburu da ni rara, ti ko si fa wahala, ati ota, abi ki o fa darudapo ti ko ba eto isuna ati ajosepo awujo lo;
1. Ona akoko: Kikere awon ona imuni leru, leyin igba ti o ti je eyi ti o po, lare awon ona wonyi ni;
* Ogun jija, ni gbogbo ona ti o pin si, gbogbo awon ti Islamu ba ba jagun ti won si bori won, won wa laarin nkan meji; yala pipa, tabi imuni-lerun.
* Ainikapa onigbese lati san gbese re fun eniti o je ni gbese.
3. Ikapa awon baba lori awon omo, eleyi ti o fun ni anfaani lati ta awon omo won, yala okunrin tabi obirin.
4. Ijawo-eni kuro nibi ominira, eleyi ti o wa ni ikapa apakan awon eniyan nitori butaka lati ta ara-won di owo kan.
5. Eru binrin ati awon ti won bo si owo ofin, won yoo ma lo idajo eru le won lori, won yoo si mu won leru.
6. Dida apakan awon ese, gegebi ipaniyan, ole jija, ati sina sise, nigbati o sepe won yoo je won ni iya ese, won yoo tun so won di eru fun eniti won se aburu si, tabi awon alasunmo re.
Awon wonyi ni die ninu awon ona imuni-leru ti o sepe awon eniyan nlo nigbati Islamu de, ti o si se gbogbo re ni eewo ayafi awon ti won ba ko leru loju ogun nikan, awon eniti won ba ko ni oju ogun ti o ba ilana ofin sharia mu, ti imam (oludari) awon musulumi kede re, ti o si pa ase re. Ki o di mimo pe awon ti won ko wonyi ko le di eru, titi Imam yoo fi so won di eru.
Nigbati o se pe gbogbo eniti a ko loju ogun ko ni eru ninu islamu, o seese ki won tu won sile lai gba nkankan lowo won, tabi ki won se pasi paaro pelu musulumi ti o wa ni igbekun eru (lodo awon keferi), tabi pelu owo, nitori oro Olohun to so bayi pe:
"...فَإِمَّا مَنًّا بَعْدُ وَإِمَّا فِدَاءً حَتَّى تَضَعَ الْحَرْبُ أَوْزَارَهَا... "
Itumo: ..Leyinna ninu ki e da won sile, tabi ki won fi nkan ra ara won titi ogun yio fi pari.." Suratu Muhammad:4.
Ninu ogbon ni aye yi ni ki won pe ki won maa tu awon eniti won ko ni oju ogun pelu ota sile nigbati o sepe awon musulumi ti awon ota ko leru nbe ni igbekun.

* Ona elekeji ti Islamu lo lati fi opin si imuni leru: Gbigbooro oju-ona itusile kuro ni igbekun eru, leyin ti o jepe ona kan pere ni o wa fun tele, eleyi tii se fife olowo-eru lati tu eru ti nbe labe re sile tabi ki o ye imunisin lori re (eru) ati awon omo re di igba ti Olohun ba fe. Sugbon nigba ti Islamu de o se agbekale ona meji fun itusile kuro ni igbekun eru, (a) Itusile laigba nkankan lowo eru, ati (b) ki eru ra ara re kuro loko eru.
Itusile eru lai gba nkan lowo re ninu Islamu ni orisirisi ona ati aworan, leyi ti o jepe ona kan soso lo wa fun tel; eyi tiise fife oga lati tu eru re sile. Ninu awon ona ti Islamu gbe kale niwonyi:
* O se itu eru sile ni okan ninu awon ona ipa apakan ese re, o si se agbekale owo-diya (owo-emi) fun ipaniyan pelu asise, ti won yoo fun awon ara-ile eniti won pa, ati titu eru kan ti o je musulumi sile kuro ni igbekun eru, nitori oro Olohun ti o so bayi pe:
" وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ أَنْ يَقْتُلَ مُؤْمِنًا إِلَّا خَطَأً وَمَنْ قَتَلَ مُؤْمِنًا خَطَأً فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ وَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَى أَهْلِهِ إِلَّا أَنْ يَصَّدَّقُوا "
Itumo:" Ko leto fun olugbagbo ododo kan ki o pa olugbagbo ododo kan ayafi pelu asise, eniti o ba pa olugbagbo ododo kan ni ona asise, ki o so eru kan ti o je olugbagbo ododo di omoluwabi, ki o si san owo-emi fun awon eniti o pa eni won, ayafi ti won ba fi tore (fun u)..) Suratu Nisai:92.
* Bakanna ni o se itu eru sile ni itanran ifi eyin iya eni we ti iyawo eni, nitori oro Olohun ti o sope:
" وَالَّذِينَ يُظَاهِرُونَ مِنْ نِسَائِهِمْ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا قَالُوا فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَتَمَاسَّا ذَلِكُمْ تُوعَظُونَ بِهِ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ (3) "
Itumo:" Atipe awon eniti won fi eyin iyawo won we ti iya won, leyinna ti won wa fe pada si oun ti won so, nigbana won yoo so eru kan di olominira siwaju ki won to le fowo kan ara won, awon yi a se ikilo fun yin nipa re, Olohun mo nipa oun ti e nse nise." Suratu Mujadalah:3.
* Bakanna ni o se itusi eru ni itanran ibura, nitori oro Olohun ti o so bayi pe:
" لَا يُؤَاخِذُكُمُ اللَّهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَكِنْ يُؤَاخِذُكُمْ بِمَا عَقَّدْتُمُ الْأَيْمَانَ فَكَفَّارَتُهُ إِطْعَامُ عَشَرَةِ مَسَاكِينَ مِنْ أَوْسَطِ مَا تُطْعِمُونَ أَهْلِيكُمْ أَوْ كِسْوَتُهُمْ أَوْ تَحْرِيرُ رَقَبَةٍ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ ذَلِكَ كَفَّارَةُ أَيْمَانِكُمْ إِذَا حَلَفْتُمْ وَاحْفَظُوا أَيْمَانَكُمْ
Itumo:" Olohun O ni je yin niya fun ibura ti e bu niti ere, sugbon On yoo mu yin fun ibura ti e finnufindo bu, nitorina itanran re ni bibo talika mewa ni aboyo ninu onje ti o dara ju ti e nfun awon ara ile yin, tabi wiwo won laso, tabi ki e so eru kan di omoluwabi, eniti ko ba ri (ti ko ni ikapa ikankan ninu awon eleyi) ki o gba awe ojo-meta, eyi ni itanran ibura yin nigbati e ba bura, e ma mu ibura yin se…" Suratu Maida:89.
* Bakanna ni o se itusile eru ni itanran asepo pelu obinrin ni osan awe Ramadana, nitori itan arakunrin saabe eleyi ti o wa si odo Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ti o sope: Ire ojise Olohun! Nipaapa mo ti pa re! Ojise Olohun ba sope: ki ni oun ti o sele si o" o sope: mo sunmo obinrin mii nigbati mo ngba awe lowo. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- sope: nje o ri eru kan ti o le so di omoluwabi bi? O sope: rara~ Ojise Olohun tun sope: nje o ni ikapa ati gba awe osu meji ni telentele? Arakunrin naa sope: rara! Ojise Olohun-ki ike Olohun ma ba- sope: nje o ri oun ti o le fi bo ogota talika? Arakunrin naa sope: rara. O sope: Ojise Olohun ba da ke, larin igba ti a fi wa bayi ni won ba wa gbe apere ti eso tamuru wa ninu re wa fun ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- Ojise Olohun ba sope: onibeere da" o ba sope: emi ni yi" ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ba sope: gba lo fi se itore" Ni arakunrin naa ba sope: ire ojise Olohun! Mo fi Olohun bura ko si laarin oke ilu Madina idile kan ti o je alaini to idile mi, ojise Olohun ba bu si erin titi eyin ogan re fi han sita, leyinna o sope: lo fi bo awon ara-ile re." Al-Bukhari.
Ki o di mimo pe dajudaju eniti okan ninu awon itanran wonyi ba je oranyan le lori ti ko si si eru kankan ti yoo tu sile ni igbekun eru, ti o wa ni ikapa ki ora eru kan, o je dandan le lori ki o ra eru naa, ki o si tu u sile kuro ni oko eru.
Islamu se siso eru di omoluwabi ni okan ninu awon ise ti o dara julo ti Musulumi fi ma nsunmo Oluwa re. Olohun so bayi pe:
" فَلَا اقْتَحَمَ الْعَقَبَةَ (11) وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْعَقَبَةُ (12) فَكُّ رَقَبَةٍ (13) أَوْ إِطْعَامٌ فِي يَوْمٍ ذِي مَسْغَبَةٍ (14)"
Itumo: " Ki lode ti ko sure si oju ona oke lati pan * ki o le mu o mo oke naa * On na ki o so eru di omoluwabi. * tabi fifun awon eniyan ni ounje je ni ojo ebi" Suratu Al-balad: 11-14.
Koda dajudaju awon oro ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ni afikun si oro re je ohun ti nseni loju oyin lati so awon eru di omoluwabi. Nigbati o sepe ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ti sope: eniti o ba tu eru kan kuro ni igbekun eru, Olohun yoo tu oun naa pelu eya kookan ninu eya ara eru naa kuro ninu ina, koda ti o fi dori abe re pelu abe re. Bukhari ati Muslim.
"At-tadbeeru" eyi ti o tumo si ki oga eru so gbangba, tabi pelu gbolohun ti yoo se afihan pe eru yoo di omoluwabi leyin iku oun, ti didi omoluwabi eru naa yoo di oun amuse leyin iku oga re. Ati nitori ki Islamu le so eto eru ni iru asiko yi ni o fi se tita tabi fifi iru eru bayi toro ni eewo.
* O se siso awon eru di omoluwabi ni okan ninu ibi ti a o maa na owo zakah si, nitori oro Olohun to so bayi pe:
" إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاءِ وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Itumo:" Dajudaju owo zakah wa fun awon talika, ati awon alaini, ati awon ti nsise re (lati gba jo), ati awon ti okan won fa si Islamu, ati fun irapada awon eru, ati fun awon ti won je gbese, ati oju ona Olohun, ati fun omo oju-ona, oranyan ni lati odo Olohun, Olohun ni Olumo Ologbon.
* Islamu se nina eru, tabi gbigbaa leti ni okan ninu okunfa itusile re, nitori oro Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ti o sope: eniti o gba omo-odo re leti, tabi o na a, itanran re ni ki o so di omoluwabi." Muslim.
Sugbon " Al-Mukaatabah" oun ni ki eru ko beere lowo oga re pe oun fe ra ominira oun ni iye owo kan ti awon mejeji yoo jo fi enu ko le lori. Nigbakugba ti eru ba beere lowo oga re pe oun fe ra ara oun, o di dandan lorun oga re ki o gba fun un. Leyin ti o ba ti ra ara re kuro loko eru, o ni eto si rira tita, ati nini dukia, ati lati se ise lati ri owo ti won jo fi enu ko le lori. Ise ti o ba se ni asiko yi lodo oga re yoo je eyi ti yoo gba owo ise le lori.
koda Islamu se wa ni oju-oyin sise saara fun iru awon bayi, ati lati ranwon lowo, yala lati odo oga won pelu pe ki oga re mu die ninu owo ti o fi ra ara re kuro fun un, tabi ki o fi awon ona kan han ti yoo ran an lowo lati san gbese ti o wa ni orun re, tabi lati odo awon Musulumi pelu pe ki won ran awon omo-iya won lowo lati di omoluwabi, ati ki won le ba kuro ni igbekun eru, nititori oro Olohun ti ola re ga julo ti O so bayi pe:
" وَالَّذِينَ يَبْتَغُونَ الْكِتَابَ مِمَّا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ فَكَاتِبُوهُمْ إِنْ عَلِمْتُمْ فِيهِمْ خَيْرًا وَآتُوهُمْ مِنْ مَالِ اللَّهِ الَّذِي آتَاكُمْ "
Itumo:"…Atipe awon eniti won ba nwa iwe ominira ninu awon ti eni ikapa lori won, e ko iwe naa fun won ti e ba mo amodaju oore ni ara won, ki e si fun won ninu owo Olohun eyi ti O se fun yin.." Suratu Nur:32.
Ni soki, a le sope dajudaju Islamu ko fe imunisin, atipe o wa pelu awon ofin ti o ko ipa ti o yanju ti o si ni ilapa nibi kikasenle imunisin.
Nipaapa ofiisi alakoso idajo ni orile Saudi arabia se eto awon ipepe iforowero meta laarin osu keji safar ni odun 1392 hijiri ti awon omo ilu Saudi si ko pa nibe, awon olukopa ni; minisita ti o wa fun ofiisi isakoso idajo nigbana, ati opolopo ninu awon oni-mimo ati awon oluko ile-eko giga ni ilu Saudi, ati awon merin ninu awon oluko eto ofin lati ile-oyinbo, awon ni;
* Alakoso ajose laarin ilu miran ti ile Irelandi ti o koja, ati akowe ajo-asofin ti ile oyinbo.
* Okan ninu awon olu keko Islamu ti kii se musulumi ati ninu awon oluko eko islamu.
* Okan ninu awon oluko ofin apapo, ati oludari iwe iroyin agbaye fun eto omoniyan ti ile faranse ma ngbe jade.
* Ati ninu awon agbalagba agbejoro ni ile-ejo ni ilu parisi.
Won se alaye nibi ijoko yi nipa kini agboye esin lodo awon Musulumi, ati lodo awon elomiran ti won kii se musulumi, won si se alaye iyato laarin awon opo apapo ti o rinle ninu ofin sharia ti Islamu ati larin awon idajo eleyo kookan inu re, won si se afihan pe ofin sharia je ofin ti o nso awon ogidi anfaani omoniyan ninu oun ti o ko sinu, ati awon opo re. Won si tun se alaye pe dajudaju awon ijiya oni-ala lori awon iwa ese ti o ni ewu je oselu-iwa odaran ti o dara ti o nso ifokanbale omoniyan, ti o si nko adinku ba iwa odaran, ati sise awewa pelu emi omoniyan ati ije omoluwabi re ati dukia re.
Nipaapa awon ti won wa si ibi akojo yi lati ile-oyinbo se afihan iyalenu won si oun ti won gbo nipa ofin sharia Islamu ati ipa re lori eto omoniyan. Olori awon iko alejo yi ti oruko re nje " Mac pride " sope Lati ibiyi ati lati ilu Islamu yi ni o ye ki won ti se ikede eto omoniyan si aye, koye koje lati ibomiran, atipe o je dandan lorun awon Onimimo Musulumi ki won se ikede awon eto yi ti o je oun ti o sokunkun si opolopo awon eniyan agbaye. Eleyi ti o sepe aimokan nipa re je okunfa fifi abuku kan oruko esin Islamu ati awon Musulumi, ati idajo inu Islamu. (oro yi wa ninu iwe "Islam ati eto omoniyan ti Dokita Abdullahi omo Abdul-Muhsin at-turki)

Oro ipari
Ni ipari, mo le sope n ko so asodun, ti mo ba sope gbogbo oun ti o wa ninu iwe kekere yi je ilaniloju nipa awon eto omoniyan ti o wa ninu esin Islamu, ki o ba le je kokoro ati itaniji fun eniti o ba kaa lati le wa alekun imo nipa titobi esin Islam, eyi ti opolopo awon eniti won npe apemora re ti fi abuku kan siwaju ki awon ota to fi abuku kan an.
Eleyi je ipepe ti a da oju re ko oluka iwe kekere yi ninu awon ti kii se musulumi pe ki won je ki esin Islamu ko ipin kan ninu awon oun kika won, ki kika yi si je ninu awon iwe ti o rinle ti o je iwe ododo. Leyin naa ki o wa se afiwe laarin oun ti o ka ati oun ti o gbo, ati oun ti o ni adisokan re, ki o si jina si eyameya eleyi ti kii je ki eniyan ri ododo, ti o si ma nyi osunwon pada. Ki a si loo mo pe kosi ere adani kankan fun wa nibi pipe awon eniyan si inu Islamu, tabi igbadun aye kan, bikosepe nitori fiferan daradara fun gbogbo omoniyan.
Dajudaju esin Islamu lati akoko igba re titi di asiko yi koye kogbo ni esin ti awon oluyapa si ngbe ogun, ti won si kojo nitori re (ogun lori re), pelu gbogbo ohun ti won ni ni agabara omoniyan ati owo. Sugbon pelu gbogbo eleyi won ko ni ikapa kankan lori Islamu bikosepe ki won ti iruju kan ti ko lesenle siwaju lodo awon eniti won je oni-lakaye ti o peye ati okan ti o ri ran. Awon ti won je oni-lakaye ti o peye ninu awon ti kii se musulumi won koye-kogbo ni eniti ti won nse opinya laarin otito ati oun ti o yato si, koda ninu awon agba alufa esin ninu awon esin miran ni onka won nlekun si nibi wiwo inu esin Islamu, laisi iyemeji eleyi je eri lori titobi esin Islamu, atipe dajudaju o je esin ododo ti o wa lati odo Olohun Eniti O se afirinle iso Re lori Islamu nigbati O so bayi pe:
إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ"
Itumo:" dajudaju Awa ni A so iranti (alu-kur'anu) kale, atipe dajudaju Awa ni A je Oluso fun un." Suratu Hijri:9.
Ni ipari oro wa, ninu awon oro Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ti o fi nse alaye nipa inife dada fun omoniyan: " eniti Olohun nife si julo ni oluse-anfani julo fun omoniyan, ise ti Olohun ti ola Re ga julo nife si julo ni idunu ti o mu de etigbo Musulumi, tabi ki o mu aburu kan kuro fun un, tabi ki o ba san gbese kan, tabi ki o ti ebi danu fun un (ki o fun ni ounje), atipe dajudaju kin wa pelu omo-iya mi ti o je musulumi lati ba gbo bukata kan re je oun ti mo nife si ju ki nse atipo osun kan ninu masalasi lo, eniti o ba gbe ibinu mi, Olohun yoo bo ihoho re (yoo fi orijin ninu ese), eniti o ba pa ibinu mo ra, ti o sepe ti o ba fe bi, yoo bi, Olohun yoo kun okan re ni ojo igbede pelu ifokanbale, enikeni ti o ba wa pelu omo-iya re muslumi lati ba gbo bukata re, titi o fi ba gbo o, Olohun yoo fi ese re rinle ni ojo ti awon ese yoo ma ye, dajudaju eda to buru julo yoo maa ba ise je gegebi oti kikan se ma nba oyin je.
Tabarani, ati Abu Duniya ni won gba wa, Al-Banni si sope Hadithu ti o dara ni.

 
www.islamland.com