IJE ERU ATI IJO ALAI GBA ESIN KANKAN GBO

IJE ERU ATI IJO ALAI GBA ESIN KANKAN GBO

IJE ERU ATI IJO ALAI GBA ESIN KANKAN GBO

العبودية واللادينية باللغة اليوروبا

 

 

Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha

د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 

 

Itumo ni ede Yoruba

European Islamic Research Center (EIRC)

المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية

& Ridwanu Allah Murtadho

Atunto

Abd Ar-Razzaq Isa

 

www.islamland.com

 

بسم الله الرحمن الرحيم

Ni oruko olohun oba ajoke aye asake orun

ORO ITISIWAJU

Ope fun Olohun oba ti o ran anabi Muhammad - (ki ike ati ola Olohun maa ba) – ni ise, ki o le je olufunni ni iro idunnu, olukilo funni, ati olu pepe si oju ona Olohun pelu iyonda Re, ki o si le je atupa ti nse imole, O si gbe ola topo fun awon saabe re, ki Olohun se ike topo ati ola fun anabi Muhammad ati awon ara ile re, ati awon saabe re.

Mo ka tira yi ti Dr. Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem As-shaiha ko, mosi gbadun gbogbo ntoko sinu, latara ohun ti mori ninu awon nkan ti o je iwosan fun awon opolopo isoro ti o lewu ni aaye ode oni, ohun naa ni: ijina si ije eru fun Olohun ni kan, ti ijina yii si ni asunta ati awon okunfa, ati awon aketun. Nbe ninu re eyi ti o je aini igbagbo ninu esin Kankan ni o faa, tabi aini imo nipa Olohun, tabi aini igbaagbo si Olohun, osi wa ninu re nto je wipe asa ilu ni o faa, nigbati o sepe awon eniyan n moju ti won si n lele pelu awon asa ise sise ati iko owo ati omo jo, ti won si ni akakun awon nkan igbadun aye, ti won ko si ni akakun nipa isunmo Oba adeda.

A ma ijina si ododo ti awon alaini igbaagbo ninu esin Kankan moti pade ogoro ninu awon olutele ilana yii, mo si se alaye fun won pe dajudaju ilana aini igbaagbo si esin Kankan yii je ilana esin bakaana, awon wonyi tako gbogbo nti nje esin patapata, won si ni adisokan wipe kosi eri Kankan fun, sugbon won ni igbaagbo si bibe Oluwa fun agbaye yii, sugbon O jina si awon eda. Bayi ni won fi esin ti o yato si esin Olohun lele fun ara won, mowa ri wipe ohun apapo larin won ni gbigba ona ti ki se ti Islam eleyi ti o wa mu won se idajo nipa esin Islam pelu asise, latara kika nipa esin kiristeni.

E o ri awon ijo alai mo Olohun ti won o ma pe agbara Olohun ni iro, beeni won si o gba a lododo, won wa n sope ni igba ti a o ri eri ti o rinle, a o le so pato nipa ipile omo eniyan, sugbon won ni igbaagbo si idagbasoke adamo, ti won si sope iseda omo-eniyan lati bi ogorun mefa milionu odun seyin wa lati ara obo, ti won ni igbaagbo ti o rinle nipa eleyi koda ki awon imo pe ni iro. Nipaapa awon nkan arisemo ori ile pe niro, ati orisirisi imo ijinle, won fi rinle iyipada ti nba igi afaala si idagbasoke awon orisirisi nkan abemi (phylogenetic tree), atipe dajudaju gbogbo nkan n losi ibi aini si mo, kii se ibi iyipada si eya miran, bakanna ni idagba soke n ba awon nkan lai yipada si eya miran, bose jepe awon kokoro kekeke ndagba soke lai yipada si eda mi i, bakanna ni o le ri eja ki o yipada si eranko ti n semi ni oke odan. Olohun so nipa idagba soke ninu al-quran ni eyi ti o han lati egberun ati ogorun merin odun si igba ti anobi (ki ike ati ola Olohun maa ba) rin irinajo esin lati makka wasi Madinah. Olohun Oba ti ola Re ga sope:

"وَقَدْ خَلَقَكُمْ أَطْوَارًا".

{Atipe dajudaju ati da yin ni igba kan layin igba}. (suuratu nuuh:14)

Ki o le kan nipa fun wa ohun ti nje igbese kan sikeji, o ri omode leyin igba die ti yoo ti di okunrin, beeni omo kinnihun leyin igba die ani eyin ogan ti o ni agbara, irori arakunrin (Darwin) kole je imo, a o le woye si, koda a o le muu lo ni alo tun lo titi ti yio fi ba oju ona mimo mu, tani eni naa ti yio sope kosi ohun ti n je esin, atipe dajudaju ile aaye o le teba fun ofin kankan ayafi awon agbelero ofin? A o sofun pe tani eni ti o ko awon ofin wonyi? Iroyin lasan ni awon ofin naa, ofin arakunrin (newton) eyi ti nfa emi ko da nkankan, nitoripe awon ofin o le da nkankan, bose jepe ko rorun lati ko owo jo lati abajade isiro, kosi atako larin igba Olohun gbo lodood ati sise alaye aye pelu awon ofin ijinle mimo, lailai ofin o le di Adeda, beeni kole da ato eyi ti ndi omo.

 

Ipepe lati inu okan lo si ibi iseri pada si esin Olohun

N be ninu awon eniyan eni ti n tako ijosin fun Olohun Oba ojoke aye, ti yoo si ma so bayi pe: tori kini elese yi o fi jiya ni ojo ikehin? Se eleyi ko tako iroyin ike Olohun bi? A o fun lesi pe: tori kini iwo naa fin je niya eni ti o tenbelu omoluwabi re tabi ba nkan ini re je? N je o ni deru ba tabi ki o gbe lo ile ejo tabi ki o ti mole fun igba die lati gba esan ise ibi re? nje o ka ilekun aanu Olohun ti owa ni sisi fun oluronupiwada ni tooto? Mofi Olohun bura, enikan o ni parun si inu ina ayafi eni ti oluse motomoto olukoja ala, oluko ijosin Olohun Oba Onike, ti o si ko gbogbo oun ti n je rere, nje iwo yi o sope: se ki se obosi ni ki eja ma je egbe re ninu odo? A o wa so fun o pe: ti eja o ba mo je ara won ni, awon eja o ba ma fikunlukun pelu wa ninu oja, ati ni oke odan, eto awujo kobasi ba je, oke o ba wo lule ati awon agbegbe ile, gbogbo nkan lo pelu oye ti eni kan o mo opin re afi Eni ti o da eda. N'isin bayi seri pada si odo Oba re, ki o si gba isiti ododo lati inu okan mi, o le ba oke dogba, o le da ile lu pelu girimonkai re, ki o mo ipo agbara Oba-Oluke Olohun re oba ti o da aye ati isemi ojo ikeyin, ki o si ma tele ona ododo, ona Islam ti o je opin esin ti a so kale lati sonmo, ki o le ba esan ti o pe pade lodo Olohun ni ojo ti ao seri pa losi odo Re, ti Yoo si fi o wo si inu ogba idera gbere, ninu isemi ti a yonu si, mo sope awon iwa daada ti romi loro kuro nibi awon esin, nje laakai awon eniyan papo lori sise opinya larin awon iwa daada ati iwa aburu? Abi iyapa wa nibe niwoye si asiko si asiko, ilu silu? N je ori ofin kan ti a gbe kale fun awon iwa ti o yato si ti esin? Se o fe mo tele ife inu re ni, ti o si fe teba fun awon idajo Olohun? Ti o baribe, kilofa ti o fin teriba fun awon ofin agbelero, ti okan elomiran si le gba nitori ise ibi ti yi o wulo fun un? Mofi Olohun bura, ibaje o fonka si ori ile ati ikolu gbogbo owo (omo eniyan) ayafi lati ara gbigbe ofin Olohun jusile. Mo tun fi Olohun bura, ti a ba fun awon oluko esin Olohun ni agbara won o ba wo awon ile ijosin ati awon mosalasi, ranti ifunpinpin ati ideruba ti o sele si awon ti nse esin daada ni asiko awon eleto ti'joba (komunisti), mo tako ola Olohun ti o se fun o, ti wa fi wa tako awon owo Olohun, mo so wipe Olohun Oba Olumo kooko ati gbangba ti gbagbe wa tabi komo n ti awon eda re nse. Se ogbagbe ni, tani eni ti o se iwoson fun o ni gba ti ara re o ya, ti o si gbe aisan buruku jina si o, o si gba adura re, o si sipaya ibanuje re ti o ni agbara, o si fun o ni eyi ti o dara ninu ibugbe, iyawo ati omo, koda ti o ba fi nkankan se adanwo fun, ore ni yi o je fun o ati fun awon eda, idi eleyi, sin Olohun re, Eni ti o da orun, osupa, ati irawo ti nse imole, O si se won ni ohun ti nse afomo fun Un pelu lilo bibo won, orun koni le osupa ba,be sini awon irawo sanmo o ni gba iwaju ara won, Oun ni o da ile, ti o si fi awon oke gbunle sibe ki o mo ba mi wa riri, o si da awon ibudo ti o mu lenu ati awon odo kekeke ti o dun ki a le mu ninu e pelu irorun, nje ire o tako gbogbo eleyi, ti o si ma fi esin re ti si ogbon? Ko ribe, Mofi Oluwa Ka'bah bura, dajudaju esin islam ni esin laakai ati ogbon.

 

Ahmad Al-Ameer

 

 

 

Abere pelu oruko Olohun, Oba Ajoke aye, Asake orun.

Gbogbo ope ti Olohun ni, ike ati ola ki o mo ba Ojise Olohun, ati awon ara ile re, ati awon saabe re.

Wo ofin islam ati awon ilana re, ma wo eni ti nse Islam, iwa re, ati ise owo re

Ije eru adamo kan ni ti Olohun da omo eniyan le lori, ti won o sile moribo kuro nibe ni igba kankan, won n be larin nkan meji ti o si iketa fun, ninu ki omo eniyan je eru fun Olohun oba nikan leni ti o teriba fun Un, ti okan re yi o wa bale, ti emi re yi o si ni isinmi, Olohun oba ti ola re ga julo so bayi:

)قُلِ اللَّهَ أَعْبُدُ مُخْلِصاً لَّهُ دِينِي {14} فَاعْبُدُوا مَا شِئْتُم مِّن دُونِهِ قُلْ إِنَّ الْخَاسِرِينَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَلَا ذَلِكَ هُوَ الْخُسْرَانُ الْمُبِينُ {15} لَهُم مِّن فَوْقِهِمْ ظُلَلٌ مِّنَ النَّارِ وَمِن تَحْتِهِمْ ظُلَلٌ ذَلِكَ يُخَوِّفُ اللَّهُ بِهِ عِبَادَهُ يَا عِبَادِ فَاتَّقُونِ {16}) (سورة الزمر: 14-16)

{Sope: emi njosin fun Olohun, emi yio ma fi ododo se esin mi Fun. Ki eyin ma sin ohun ti eyin ba fe leyin Re, sope: dajudaju awon eni ti won sofo ni awon ti won sofo emi won ati awon eniyan won ni ojo ajinde, egbo o!!! iye ni ofo ti o han gbangba. Ate inan yio wa fun won ni oke ori won ati ni isale won, Olohun n fi iye deruba awon erusin Re, eyin erusin Mi ki e ma paya Mi". (suuratu-z-zumar: 14-16)

Tabi ki o je eru fun awon nkan miran ti won npe ni Olohun, bi ife-inu, awon orisa, owo, awon ofin ati awon eniyan, pelu awon eleyi emi re yoo sofo, ti okan re yoo si daru, ti yoo si pofo aye re ati ojo ikeyin re, Olohun Oba ti ola Re ga sope:

) أَفَرَأَيْتَ مَنِ اتَّخَذَ إِلَهَهُ هَوَاهُ وَأَضَلَّهُ اللَّهُ عَلَى عِلْمٍ وَخَتَمَ عَلَى سَمْعِهِ وَقَلْبِهِ وَجَعَلَ عَلَى بَصَرِهِ غِشَاوَةً فَمَن يَهْدِيهِ مِن بَعْدِ اللَّهِ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ( (الجاثية: 23)

{Nje ire ri eni ti o fi ife-inu re se Olohun re, Olohun si moomo fi sile ninu isinan, atipe Olohun fi edidi di eti re ati okan re, O si fi ebibo bo oju re? tani eni ti yio fi onan moo leyin Olohun? Se e ko ranti ni}. (suuratul jathiyah:23)

Sayid Qutub (ki Olohun se ike fun) so bayi: "dajudaju ko si iyemeji nibi ije eru! Ti ko ba je ti Olohun nikan yoo si je ti elomiran ti oyato si Olohun, ije eru fun Olohun nikan ma nso eniyan di omoluwabi, alaponle, eni-abiyi, eni-giga, bee sini ije eru fun elomiran yato si Olohun ma nje ije omoniyan awon eniyan, aponle won, ominira won ati awon ola won, leyin naa yoo tun je awon owo won ati awon nkan anfani won ni igbeyin".

Isesi iyepere ati igbafa ti kosi ife nibe ni ije eru fun eru si olowo re. Pelu agboye yi okan korira re, eti si ko lati gbo o, o si lodi si iwoye yi, sugbon ti o ba je ti Olohun Oba ti o ni agbaye yoo mu nii ri iyi, aponle ati ominira. Esin Islam de pelu papa ominira eyi ti a o ri pelu ije eru fun Olohun nikan, ije eru ti yio fi eto si gbogbo isemi, ko si abosi ati rira lare ohun ti a fun ni toju (amona) pelu gbogbo agboye re ti o pe. Olohun ti ola Re ga sope:

 )إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَنْ تُؤَدُّوا الْأَمَانَاتِ إِلَى أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُمْ بَيْنَ النَّاسِ أَنْ تَحْكُمُوا بِالْعَدْل( (النساء: 58)

{Dajudaju Olohun pa a lase fun yin pe ki e da ohun ti a fun yin toju pada fun awon ti o ni won, nigba ti e ba ndajo larin awon eniyan e da a pelu eto, dajudaju Oluwa dara ni Oluse ikilo, dajudaju Oluwa je Olugboro, Oluriran}. (suuratu-n-Nisaai:58).

 Ko si ije owo awon eniyan ni ona ibaje pelu jijale tabi sise abosi tabi gbigba owo ele, Olohun ti ola Re ga sope:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَأْكُلُوا أَمْوَالَكُمْ بَيْنَكُمْ بِالْبَاطِلِ إِلَّا أَنْ تَكُونَ تِجَارَةً عَنْ تَرَاضٍ مِنْكُمْ " (النساء: 29)

{Mope eyin ti e gbagbo! E ma se je ohun-ini yin larin ara yin pelu eru, afi ki o je owo-sise pelu iyonu yin, e ko si gbodo pa ara yin, dajudaju Olohun je Alaanu si yin}. (suuratu-n-Nisaai:29).

 Koni si isoro omoluwabi won lai da, ati tita eje ara won sile, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَالَّذِينَ لَا يَدْعُونَ مَعَ اللَّهِ إِلَهاً آخَرَ وَلَا يَقْتُلُونَ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللَّهُ إِلَّا بِالْحَقِّ وَلَا يَزْنُونَ وَمَن يَفْعَلْ ذَلِكَ يَلْقَ أَثَاماً" (الفرقان: 68).

{Atipe awon eni ti kii pe olohun miran pelu Olohun, won ki si pa emi ti Olohun se pipa re ni eewo afi pelu ododo (eto), won kii se pansaga, eni ti o ba se eyi ni yio pade idajo ese re}. (suratul furqan:68).

 Won a mo pe awon iwo (eto) latara re, gege bi Olohun se paa lase ninu oro Re:

" وَاعْبُدُواْ اللّهَ وَلاَ تُشْرِكُواْ بِهِ شَيْئاً وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً وَبِذِي الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينِ وَالْجَارِ ذِي الْقُرْبَى وَالْجَارِ الْجُنُبِ وَالصَّاحِبِ بِالجَنبِ وَابْنِ السَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ إِنَّ اللّهَ لاَ يُحِبُّ مَن كَانَ مُخْتَالاً فَخُوراً" (النساء: 36).

{ki e si maa sin Olohun, ki e si ma pa nkankan po moo, kie si maa se rere si awon obi mejeeji, ati awon ebi, ati awon omo-orukan, ati awon alaini, ati awon aladugbo ti o sunmo yin, ati awon aladugbo ti o jinnan, ati awon ore alabarin, ati omo-ojuonan, ati awon ti owo otun yin ni (ni akapa), Olohun ko fe awon onigberaga, onifaari}. (suuratu-n-Nisaai:36).

 Pelu eleyi, yio fi orijin alaburu, yio si mojukuro fun alasise, yio si kun keke fun omojukuro bi Olohun se paa lase:

 " خُذِ الْعَفْوَ وَأْمُرْ بِالْعُرْفِ وَأَعْرِضْ عَنِ الْجَاهِلِينَ" (الأعراف: 199)

{se amojukuro ki o si ma pa awon eniyan lase iwa rere, ki o si seri kuro lodo awon alaimonkan}. (suuratu-l-A'raaf:199).

Dajudaju omo eniyan ni aye ode oni nwa bukata si ominira (lenu won), o nwa itusile lai ni onde, osi fe ma se ohun ti o fe, ki o si gbeju-sile ohun ti ko fe, yato si awon musulumi ti won ko fe ominira iru eleyi, sugbon won nfe ominira eyi ti yio waye latara ije eru fun Olohun (Oba ti o mo ti ola Re ga julo), won ni eto si eleyi nitoripe ije eru yio mu won losi ibi papa ominira eyi ti enikan o ni ni ijegaba lori won, eniyan o le ri iru ominira yi beeni kosi lodo enikan ayafi lati ibi paapa ije eru ti awon ojise Olohun mu wa, awon ti Olohun gbedide ni arin asiko kan si omiran, lati le tun esin se fun awon eniyan, ati lati da won pada si odo Olohun won ti O da won, kosi ni si awijare kan fun won leyin gbigbe awon ojise yi dide, Olohun sope:

 " وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولاً أَنِ اعْبُدُواْ اللّهَ وَاجْتَنِبُواْ الطَّاغُوتَ فَمِنْهُم مَّنْ هَدَى اللّهُ وَمِنْهُم مَّنْ حَقَّتْ عَلَيْهِ الضَّلالَةُ فَسِيرُواْ فِي الأَرْضِ فَانظُرُواْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ" (النحل: 36)

{Atipe dajudaju Ati gbe ojise kookan dide ninu ijo kookan pe: kie sin Olohun, kie si jinnan si awon orisa, eni ti Olohun fi mona nbe ninu won, atipe eni ti isinan tosi n be ninu won, nitorinan ema rin ni ori-ile, leyin nan ki e ma wo bawo ni atibotan awon opuro ti ri}. (Suuratu-n-nahl:36).

Dajudaju ominira ti a tu kale ni ibamu si agboye awon oyinbo ni asiko wa yi je kantankantan niti paapa, ominira ti olowo nti atara re je dukia alaini, ti alagbara si nje gaba lori ole, ti won nfa omoluwabi ya, ti won sin je awon owo ni ije ibaje, ti won si npa awon emi, ti won ra awon iwo lare ati awon nkan oranyan, eleyi ni ominira awon eranko inu igbo, ni igba ti Olohun nbu enu ate lu eni ti o gbe sise ijosin Re ju sile, tosi tu ijanu re sile fun awon ife inu re, ati awon ohun ti nwu, Olohun salaye eleyi wipe:

 " وَلَقَدْ ذَرَأْنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيراً مِّنَ الْجِنِّ وَالإِنسِ لَهُمْ قُلُوبٌ لاَّ يَفْقَهُونَ بِهَا وَلَهُمْ أَعْيُنٌ لاَّ يُبْصِرُونَ بِهَا وَلَهُمْ آذَانٌ لاَّ يَسْمَعُونَ بِهَا أُوْلَـئِكَ كَالأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ أُوْلَـئِكَ هُمُ الْغَافِلُونَ " (الأعراف: 179)

{Dajudaju A da opolopo eniyan ati alujonu fun ina-jahannamo, nitoripe okan nbe fun won won ko fi ronu, oju si nbe fun won won ko fi reran eti si nbe fun won won ko fi gboro, awon eniwonyi dabi eran, koda won sinan ju eran lo, awon eniwonyi ni olugbagbera}. (Suuratu al-A'raaf:179).

 Gbogbo adanwo ti nsele ni agbaye loni nipa abosi, ogun, ai ni idagba soke oro-aje ati ise-ijoba, okunfa gbogbo e patapata ni ijina si ije eru lododo fun Olohun Oba ti o se awon ofin ti yio se atunse awujo ati awon eniyan inu re, gbigbaamu ati isise to ni orire fun awon eniyan lapapo, ni aye won ati ni ojo ikeyin won, bi won ba si se jinna si to ni adanwo won yio se po to ati iloseyin won, sugbon won fi ohun ti o kere paro ohun ti o lore julo, latara lilo awon ofin awon eniyan eyi ti asise re po ju iwulo re lo, ilana ti won mo lori ife-inu enii ati eto ijoba won, o si ko iparun ba won. Ododo ni Olohun so ninu oro Re wipe:

"أَلَا يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ" (الملك: 14)

{Nje eni ti o da eda ko a mo ni? Atipe Oun ni Alaanu, alamontan" (Suuratu Al-mulk:14).

Awon musulumi akoko je asiwaju gbogbo agbaye, idajo won si je ore fun gbogbo awon eniyan patapata, nigbati ije eru won je ti t'Olohun ni gbogbo agbegbe isemi won, ise-ijoba, abagbe, ihuwa ati oro aje, kosi abosi ati jije iwo ara-ilu tabi lilo nkan-ini won lona ewo, koda awon ti won ki se musulumi gbola fun idajo won lori idajo gbogbo awon elesin toku, nitori deede ti won ri nibe, eleyi yato si isesi awon musulumi oni, awon ti won gba apakan tira gbo ti won si ko apakan re, won njosin fun Olohun pelu ohun ti o ba wu won ti o si ba ife-inu won mu, won yio si gunri kuro nibi eyi ti o ba yapa si, awon ota won wa lo eleyi lati fi joba le won lori, awon ti aisan nbe ninu emi won ati ife aye, won wa ni ikapa lati mu won leru, yepere won ati lati gba awon dukia won, ododo ni Olohun so ni igba ti nse alaye eleyi:

" ذَلِكَ بِأَنَّ اللّهَ لَمْ يَكُ مُغَيِّراً نِّعْمَةً أَنْعَمَهَا عَلَى قَوْمٍ حَتَّى يُغَيِّرُواْ مَا بِأَنفُسِهِمْ وَأَنَّ اللّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ " (الأنفال: 53)

{Eyi ri be nitoripe Olohun koje yi idera ti O se fun awon eniyan kan pada, titi ti awon funrawan yio fi yi ohun ti nbe ni okan won pada, atipe dajudaju Olohun ni Olugboro, Onimimo}. (Suuratu Al-anfaal:53).

Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti kilo eleyi fun won oso wipe:

[bawo ni e o se wa ti nkan marun kan ba sele si yin? Mo wa iso ni odo Olohun ki awon nkan naa sele lati ara yin tabi loju yin, …awon apase yin o ni mo dajo pelu ohun ti o yato si Alukurani ti Olohun so kale ayafi ki Olohun fi awon ota won je gaba le won lori, ti won yio si gbag die ninu ohun ti nbe lowo won, won o ni gbe tira Olohun ati sunna ojise Re ju sile ayafi ki Olohun fi ijeniya won si aarin won". (Saheeh At-targeeb:2187).

 Eleyi ni bi awon ijo musulumi se ma wa nigbati won ba gbe ijosin Olohun ju sile, an wa Olohun ni iso kuro nibi eleyi.

 

 

 

Al-Qur'anu ati iwoye ti o kun keke nipa agbaye

Dajudaju ninu ohun ti o ko airoju ba irori eda lati lailai ni oro nipa dida agbaye ati gbogbo ohun ti nbe ninu re, esi irori yi yori si eero lasan ti o jina si paapa ati laakai, nitoripe won o mo pato bi o se je, won o si le mo ayafi lati odo Eni ti o da. Al-qur'anu wa salaye re leseese ni ona ti o ba laakai mu, okan si bale si awon ogba oro (aaya) re ti o salaye apero yi. Al-qur'anu fesi si ibere laakai awon eniyan nipa bi aye se bere ati gbogbo ohun ti nbe ninu re, ati idi pataki ti won tori re da a, ati opin re.

 

Ibere dida eniyan

Ninu ohun ti o ye ni ibere lati fi wole si inu oro yi ni oro Olohun to wipe:

 " هُوَ الْأَوَّلُ وَالْآخِرُ وَالظَّاهِرُ وَالْبَاطِنُ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ " (الحديد: 3)

{Oun ni Eni-akoko, Oun si ni Eni-igbeyin, Oun ni O han, Oun nan si ni O sunmo, Oun ni O mo gbogbo nkan}. (Suuratu Al-Hadeed:3).

 Ati gbolohun Olohun nipa ara Re:

" قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ {1} اللَّهُ الصَّمَدُ {2} لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ {3} وَلَمْ يَكُن لَّهُ كُفُواً أَحَدٌ {4}" (الإخلاص 1-4)

{Sope Oun ni Olohun Okan soso, Olohun ni Oba ti a ma nronu kan, Ko bi omo beni eni kan o Bi, Besi ni kosi eni ti o Jo}. (Suuratu Al-Ikhlas:1-4).

Dajudaju won bi ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun maa ba) nipa paapa agbaye yi ati bibe re, nigba ti awon alejo kan ninu awon ara ilu (yaman) wa ba, won sofun pe: {Awa ba o lati ni agboye nipa esin, ki asile bi o nipa bi agbaye yi se bere, o sope: "Olohun ti nbe ki gbogbo nkan to ma be, aga al arashi Re si n be ni ori omi, leyinna O da sanmo ati ile, O si ko gbogbo nkan si inu wala- kadara" (Saheeh Al-bukhaari)

 Olohun ti ola Re ga julo sope:

 " أَوَلَمْ يَرَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ كَانَتَا رَتْقاً فَفَتَقْنَاهُمَا وَجَعَلْنَا مِنَ الْمَاء كُلَّ شَيْءٍ حَيٍّ أَفَلَا يُؤْمِنُونَ " (الأنبياء: 30)

{Se awon eniti o se aigbagbo ko ri nipe dajudaju sanmo ati ile mejeji je ohun ti o papo, sugbon Awa ya won si otooto, Asi se gbogbo nkan alaaye lati inu omi, nje won ko niwa gbagbo wayi?}. (Suuratu l- anbiyai:30).

Olohun da agbaye - (awon sanmo ati ile) – gbogbo e si le papo mo ara won, o si wa ni ori ara won ni ipile, leyin naa O wa ya won lotooto, O se sanmo ni meje, O se ile ni meje, O fi ategun se ala si aarin sanmo aye ati ile, sanmo si ro ojo, ile si hu irugbin jade, Olohun ti ola Re ga sope:

 " بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَإِذَا قَضَى أَمْراً فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُن فَيَكُونُ " (البقرة :117)

{Eleda sanmo ati ile ni, ti o ba ti pinnu oro kan, yio so fun pe ki o je be, yio si je be}. (Suuratu Al-baqorah:117).

Leyin naa Olohun da Adam baba gbogbo omo-eniyan si inu ile idera (Al-jannah), O si ni ki awon malaika fi ori bale fun un, gbogbo won fi ori bale ayafi Iblisu baba awon esu, o se girimonkai lati fi ori bale, o si pinu lati se keeta Adam, eni ti Olohun ponle ti O si gbe ola fun ju lo, eleyi je ipile ota larin eniyan ati Iblisu baba awon esu, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَراً مِن طِينٍ{71} فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ{72} فَسَجَدَ الْمَلَائِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ{73} إِلَّا إِبْلِيسَ اسْتَكْبَرَ وَكَانَ مِنْ الْكَافِرِينَ{74} قَالَ يَا إِبْلِيسُ مَا مَنَعَكَ أَن تَسْجُدَ لِمَا خَلَقْتُ بِيَدَيَّ أَسْتَكْبَرْتَ أَمْ كُنتَ مِنَ الْعَالِينَ{75} قَالَ أَنَا خَيْرٌ مِّنْهُ خَلَقْتَنِي مِن نَّارٍ وَخَلَقْتَهُ مِن طِينٍ{76} قَالَ فَاخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ{77} وَإِنَّ عَلَيْكَ لَعْنَتِي إِلَى يَوْمِ الدِّينِ{78} قَالَ رَبِّ فَأَنظِرْنِي إِلَى يَوْمِ يُبْعَثُونَ{79} قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ الْمُنظَرِينَ{80} إِلَى يَوْمِ الْوَقْتِ الْمَعْلُومِ{81} قَالَ فَبِعِزَّتِكَ لَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ{82} إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ الْمُخْلَصِينَ{83} قَالَ فَالْحَقُّ وَالْحَقَّ أَقُولُ{84} لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنْهُمْ أَجْمَعِينَ{85} (سورة ص: 71-85)

{Nigba ti Oluwa re so fun awon malaika pe: dajudaju Emi fe da abara kan lati inu ere. nigbati mo ba see dogba ti Mo si fe Emi mi sinu re, nitorinan ewo lu'le niti iforikanle fun un, gbogbo awon malaika patapata si f'orikanle ayafi esu ni o se igberaga, atipe o je okan ninu awon alaigbaagbo. * (Olohun sope: kini o ko fun o ti ko je ki o fi ori kanle fun ohun ti mo fi owo Mi da, o ha se igberaga ni tabi oje okan ninu awon oni-motomoto. * O sope: emi dara ju u lo, O da mi latara ina O si da oun latara ere. * (Olohun) sope: jade kuro nibe (ninu ogba idera), nitoripe dajudaju ire je eni egbe. * Atipe egun Mi yio ma be lori re titi lo di ojo esan. (Esu) sope: Oluwa mi, lomi lara di ojo igbende. * (Olohun) sope: nigbanaa ire wa ninu awon ti A o lo lara. * Titi di ojo asiko naa ti a mo. * (Esu) sope: pelu agbara Re, dajudaju emi yio si gbogbo won lona patapata. * Ayafi awon erusin Re olododo (ti won nse afomo ijosin won fun O). * (Olohun sope: ododo niyi atipe ododo naa ni Emi nso. * Dajudaju Emi yio fi ko ina jahannama ire ati gbogbo awon ti o ba tele o ninu won}. (suuratu Sood:71-85).

Leyin naa Olohun da fun Adam iyawo re Hawwau (ki ola Olohun ba awon mejeji) ki o le fi ara bale si odo re, ki oju re si le tutu, ki o si le ma ba naju, ki won si le je ipile fun sise awon eniyan sile. Olohun ti ola Re ga sope:

" يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُواْ رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالاً كَثِيراً وَنِسَاء وَاتَّقُواْ اللّهَ الَّذِي تَسَاءلُونَ بِهِ وَالأَرْحَامَ إِنَّ اللّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيباً " (النساء: 1)

{Mo pe eyin eniyan, eberu Oluwa yin, Eni ti o se eda yin lati ara emi kan soso, O si se eda aya re lati ara re, O si tan opolopo okunrin ati obinrin kale lati ara awon mejeeji, ki e si beru Olohun Eni ti e fi n be ara yin ati okun ebi, dajudaju Olohun je Oluso lori yin}. (Suuratu An-nisaai:1).

Ogba idera (al jannah) je ibugbe awon mejeeji, Olohun si se alaye fun won pe ota won ni Iblees (Esu), nitori bee ki won sora fun un, Olohun ti ola Re ga sope:

" فَقُلْنَا يَا آدَمُ إِنَّ هَذَا عَدُوٌّ لَّكَ وَلِزَوْجِكَ فَلَا يُخْرِجَنَّكُمَا مِنَ الْجَنَّةِ فَتَشْقَى {117} إِنَّ لَكَ أَلَّا تَجُوعَ فِيهَا وَلَا تَعْرَى {118} وَأَنَّكَ لَا تَظْمَأُ فِيهَا وَلَا تَضْحَى {119}" (سورة طه:117-119)

{Nitori naa Awa sope: ire Adam, dajudaju eleyi bayi ota ni oje si ire ati aya re, nitori nan mase jeki o yo eyin mejeeji jadeninu ogba idera (al jannah) yi, ki o ma ba se oriburuku. Dajudaju ebi ko ni pa o, beeni oko ni wa ni ihoho ninu re. atipe dajudaju ongbe ko ni gbe o, beeni orun ko ni pa o ninu re}. (suuratu toha:117-119).

Olohun si pa won lase ki won maa je ki won ma gbadun pelu gbogbo ohun ti n be ninu ogba idera (al jannah) ni idekun, ayafi igi kan soso ti o ko fun won lati je ninu re, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَقُلْنَا يَا آدَمُ اسْكُنْ أَنتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ وَكُلاَ مِنْهَا رَغَداً حَيْثُ شِئْتُمَا وَلاَ تَقْرَبَا هَـذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الْظَّالِمِينَ " (البقرة :35)

{Awa wipe: Adam! Iwo ati iyawo re, e ma gbe inu ogba idera nan, ki e si ma je ninu re ni perewu, ni aye kaye ti e ba fe, sugbon e ma se sunmon igi yi ki e ma ba di ara awon alabosi}. (Suuratu Al-baqorah:35).

Esu kapa lati mu Adam (baba awon eniyan) ati iyawo re jade kuro ninu ogba idera (al jannah) pelu ete ati itanje re e ati yiyi paapa nkan pada si panda, leyin igba ti o se royiroyi si won ninu okan lati je ninu igi ti Olohun ni ki won ma je ninu re, Olohun ti ola Re ga sope:

 "فَوَسْوَسَ إِلَيْهِ الشَّيْطَانُ قَالَ يَا آدَمُ هَلْ أَدُلُّكَ عَلَى شَجَرَةِ الْخُلْدِ وَمُلْكٍ لَّا يَبْلَى {120} فَأَكَلَا مِنْهَا فَبَدَتْ لَهُمَا سَوْآتُهُمَا وَطَفِقَا يَخْصِفَانِ عَلَيْهِمَا مِن وَرَقِ الْجَنَّةِ وَعَصَى آدَمُ رَبَّهُ فَغَوَى {121} ثُمَّ اجْتَبَاهُ رَبُّهُ فَتَابَ عَلَيْهِ وَهَدَى {122}" (سورة طه:120-122)

{Esu si ko erokero si lokan, o wipe: ire Adam se ki emi fi igi (ti yio mu o wa) gbere han o, ati ijoba ti koni lopin? Nitori nana won mejeeji si je ninu re, nigbanan ihoho awon mejeeji si han si won, awon mejeeji bere si ni le nini ewe ogba na mo ara won, Adam si se aigboro si Oluwa re, o si koja ala. Leyin nan Oluwa re saa lesa, O si gba ituba re, O si to o sonan}. (suuratu toha:120-122).

Iya ese Adam (ki ola Olohun o maa ba) ati iyawo re je mimu won jade kuro ninu ogba idera (Al-Jannah), ati siso won kale si orile ti Olohun won ti da siwaju, ki o le je ibugbe won ati awon aromodomo won, ki o si je ile idanwo fun won, Olohun ti ola Re ga sope:

 " قُلْنَا اهْبِطُواْ مِنْهَا جَمِيعاً فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدًى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ {38} وَالَّذِينَ كَفَرواْ وَكَذَّبُواْ بِآيَاتِنَا أُولَـئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ {39} (سورة البقرة:38-39)

{Awa wipe: e sokale kuro ninu re patapata, nitoripe dajudaju itosonan yio ma de wa ba yin lati odo Mi, nigbanaa enikeni ti o ba tele itosona Mi, iberu ki yio si fun won, won ki yio si banuje. * Atipe Awon ti won se aigbagbo ti won si pe awon aami Wa ni'ro, gbogbo awon wonyi ni ero inan, won yio si ma gbe ibe lailai}. (suuratu Al-baqorah:38-39).

Pelu ijade won ninu ogba idera (Al-Jannah) ati isokale won si ori ile ni ota bere larin won ati Esu, o si bere si ni mu awon ipalese re e ti o se ileri re fun Adam ati awon aromodomo re se, leyin igba ti o jade kuro ninu ogba idera (al jannah) ti o si so kale si ori ile, Olohun so wipe:

" قَالَ يَا إِبْلِيسُ مَا لَكَ أَلاَّ تَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ{32} قَالَ لَمْ أَكُن لِّأَسْجُدَ لِبَشَرٍ خَلَقْتَهُ مِن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ{33} قَالَ فَاخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ{34} وَإِنَّ عَلَيْكَ اللَّعْنَةَ إِلَى يَوْمِ الدِّينِ{35} قَالَ رَبِّ فَأَنظِرْنِي إِلَى يَوْمِ يُبْعَثُونَ{36} قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ الْمُنظَرِينَ{37} إِلَى يَومِ الْوَقْتِ الْمَعْلُومِ{38} قَالَ رَبِّ بِمَا أَغْوَيْتَنِي لأُزَيِّنَنَّ لَهُمْ فِي الأَرْضِ وَلأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ{39} إِلاَّ عِبَادَكَ مِنْهُمُ الْمُخْلَصِينَ{40} قَالَ هَذَا صِرَاطٌ عَلَيَّ مُسْتَقِيمٌ{41} إِنَّ عِبَادِي لَيْسَ لَكَ عَلَيْهِمْ سُلْطَانٌ إِلاَّ مَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْغَاوِينَ{42} وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمَوْعِدُهُمْ أَجْمَعِينَ{43} (سورة الحجر32-43)

{O (Oluwa) si wipe: ire ibilisu (esu) ki ni o se o ti ire ko ma be pelu awon ti o teriba? * O si wipe: emi koje teriba fun abara kan ti o da eda re ninu amo ti o gbe, ti o si dudu, ti a yi pada si eda. * (Oluwa si wipe: nitorina jade kuro ninu re (ogba idera), atipe iwo di eni egbe. * Atipe egun yoo wa lori re titi di ojo esan. * O si wipe; Oluwa mi! lora fun mi di ojo ti a o gbe won (eniyan) dide. * O (Olohun) wipe: dajudaju ire yio ma be ninu awon eni ti a lora fun un. * Di ojo asiko ti a mo. * O (ibilisu) wipe: Oluwa! Pelu pe o so mi nu, dajudaju emi yio se awon nkan aburu loso fun won lori ile, atipe emi yio so gbogbo won di eni anu. * Ayafi awon erusin re ninu won ti a fo mo. * O (Olohun) wipe eyi je oju-ona kan ti o to lodo Mi. * Dajudaju awon erusin mi agbara kan koni si fun o lori won, ayafi eni ti o ba tele o ninu awon eni anu. * Atipe dajudaju ina jahannamah ni aye adeun won lapapo}. (suuratu Al-hijr:32-43).

Awon eniyan ni ipile ijo kan naa ni won, won wa bere si ni po, won si fonka ori ile lati sise wa ije imu won, Olohun ti ola Re ga julo sope:

 " كَانَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً فَبَعَثَ اللّهُ النَّبِيِّينَ مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ وَأَنزَلَ مَعَهُمُ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ لِيَحْكُمَ بَيْنَ النَّاسِ فِيمَا اخْتَلَفُواْ فِيهِ " (البقرة :213)

{Gbogbo awon eniyan je ijo kan soso, Olohun wa gbe awon anobi dide ni olufunni-niro-iduunu ati olukilo-funni, O si so awon tira na kale fun won pelu ododo, ki o ba se idajo laarin awon eniyan nipa ohun ti won nse iyapa enu si}. (Suuratu Al-baqorah:213).

Latara pipo yi won wa fonka si ori ile, Olohun wa ran awon ojise si awon eniyan yii ti won fonka ori'le latara dede Re, ki won ba je olufunni-niro-iduunu ati olukilo-funni, ki won le da won pada si ibi adiokan won ti o ni alaafia ati esin won ti o je ipile, ki won si le je orojare lori won, Olohun ti ola Re ga sope:

 " رُّسُلاً مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلاَّ يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى اللّهِ حُجَّةٌ بَعْدَ الرُّسُلِ وَكَانَ اللّهُ عَزِيزاً حَكِيما" (النساء: 165)

{Awon ojise kan ti won je oniro-idunnu ati oluse-ikilo, nitori ki awijare ma se ma be fun awon eniyan lodo Olohun leyin (riran) awon ojise, Olohun je Alagbara Ologbon}. (n niaasi:165)

Eni ti o ba gba ohun ti awon ojise yii mu de lati odo Olohun ti o si tele won yio wo ogba idera (Al-Jannah), eni ti o ba si ko ohun ti won mu de ti o se igberaga yio wo inu ina, Olohun ti ola Re ga sope:

" يابَنِي آدَمَ إِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ رُسُلٌ مِّنكُمْ يَقُصُّونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِي فَمَنِ اتَّقَى وَأَصْلَحَ فَلاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ {35} وَالَّذِينَ كَذَّبُواْ بِآيَاتِنَا وَاسْتَكْبَرُواْ عَنْهَا أُوْلَـَئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ {36}" (سورة الأعراف:35-36)

{Eyin omo Adam! Nigba ti awon ojise ba wa ba yin ninu yin, ti won nke awon ayah Mi fun yin, enikeni ti o ba paya ti o se daada koni si iberu fun won, won ko si ni banuje. Awon eni ti won npe awon ami Wa niro, ti won si fi igberaga seri kuro nibe, awon wonyi ni ero inan, won yio se gbere ninu re}. (suuratul-Aaroof:35-36).

 Olohun ti ola Re ga si tun sope:

وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ (6) إِذَا أُلْقُوا فِيهَا سَمِعُوا لَهَا شَهِيقًا وَهِيَ تَفُورُ (7) تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ الْغَيْظِ كُلَّمَا أُلْقِيَ فِيهَا فَوْجٌ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌ (8) قَالُوا بَلَى قَدْ جَاءَنَا نَذِيرٌ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ اللَّهُ مِنْ شَيْءٍ إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ كَبِيرٍ (9) وَقَالُوا لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِي أَصْحَابِ السَّعِيرِ (10) فَاعْتَرَفُوا بِذَنْبِهِمْ فَسُحْقًا لِأَصْحَابِ السَّعِيرِ (11) إِنَّ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ بِالْغَيْبِ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ (12)" (سورة الملك: 6-12)

{Iya jahannama si nbe fun awon eni ti won se aigbagbo si Oluwa won, o si buru ni apadasi. * Nigba ti won ba ju won sinu re, won yio ma gbo kikun ina naa, ti yio ma ru soke. * Yio fe pin latara ibinu, igba yio wu ti won ba ju ijo kan sinu re, awon oluso ibe yio ma bi won lere pe: nje olukilo kan ko wa ba yin bi? * Won o sope: bee ni, dajudaju olukilo kan ti wa bawa, sugbon a pe ni opuro a si sope: Olohun ko so kinnikan kale, eyin ko wa ninu kinnikan ju isina ti o tobi lo. * Atipe won a tun sope: ti o ba sepe awa gboran ni tabi ti a si lo laakaye, a ki ba ti wa ninu ero ina jonijoni. * Dajudaju awon eni ti won paya Oluwa won ni koko, aforijin yio ma be fun won ati esan ti o tobi}. (suuratul mulk:6-12).

(Awon ojise yi) ran awon ijo won leti ota ti nbe laarin won ati Esu, won si nkilo fun won pe ki won ma je ki o seri won pada kuro ni ona ti o to, eyi ti Olohun yonu si fun won ti O si salaye re lati enu awon ojise Re ati awon anobi Re, ti won yio fi wa ma tele ife-inu won ati ero okan won, ti yio fi wa se ibaje loso fun won, Olohun ti ola Re ga sope:

" يَا بَنِي آدَمَ لاَ يَفْتِنَنَّكُمُ الشَّيْطَانُ كَمَا أَخْرَجَ أَبَوَيْكُم مِّنَ الْجَنَّةِ يَنزِعُ عَنْهُمَا لِبَاسَهُمَا لِيُرِيَهُمَا سَوْءَاتِهِمَا إِنَّهُ يَرَاكُمْ هُوَ وَقَبِيلُهُ مِنْ حَيْثُ لاَ تَرَوْنَهُمْ إِنَّا جَعَلْنَا الشَّيَاطِينَ أَوْلِيَاء لِلَّذِينَ لاَ يُؤْمِنُونَ {27} " (سورة الأعراف:27)

{Eyin omo Adam! E ma se jeki esu si yin lonan gege bi o ti se yo awon obi yin mejeeji jade kuro ninu ogba idera, ti o bo aso kuro lara won ki o le fi ihoho won han won, dajudaju oun ati awon omo ogun re nri yin ni aye ti eko ri won, Awa ti se esu ni oro fun awon eni ti ko Gbagbo}. (suuratul Aaroof:27).

 

Ogbon (ati oye) ti o wa nibi dida awon eniyan:

Ninu ohun ti o han gedegbe nipe eniyan ko ni lo ojo-ori re, asiko re, igbiyanju re ati owo re fun sise nkankan ayafi nitori ati ri anfani kan tabi lati da inira kan pada, bee naa ni Olohun ti o ni apejuwe ti o ga julo, ko da awon eda lasan, ko si fi won sile lai si iwulo, Olohun ti ola Re ga sope:

" أفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثاً وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ {115} فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ {116}" ( سورة المؤمنون:115-116)

{Nigbana e ha ro pe a da yin lasan ni, Atipe A ko ni da yin pada si odo Wa nibi? * Gbigbongbon Olohun, Oba ododo, ko si Olohun miran ayafi oun naa, Oluwa Oni ite-alaponle}. (suuratul muhmineen:115-116).

Olohun ko da agbaye yi ati gbogbo ohun ti o wa ninu re fun ere, mimo fun Olohun nibi eleyi, sugbon O da a nitori idi pataki, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاء وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَاعِبِينَ {16} لَوْ أَرَدْنَا أَن نَّتَّخِذَ لَهْواً لَّاتَّخَذْنَاهُ مِن لَّدُنَّا إِن كُنَّا فَاعِلِينَ {17}" ( سورة الأنبياء:16-17)

{Atipe Awa ko da sanmo ati ile ati ohun ti nbe laarin won nitori ere sise * Ti o ba sepe Abafe lati ma se ere ni a ba mu ere naa se lati odo Wa, bi Awa ba je olusere". (suuratul anbiyaah:16-17).

Olohun ko da awon eniyan ti a gbola fun lori gbogbo awon eda, ko si fi won se arole lori ile ayafi nitori ki won le mojuto oranyan kan pato ti won tori re da won, Olohun salaye eleyi ninu oro Re wipe:

" وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ (56) مَا أُرِيدُ مِنْهُم مِّن رِّزْقٍ وَمَا أُرِيدُ أَن يُطْعِمُونِ (57) إِنَّ اللَّهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ (58) " (سورة الذاريات:56-58)

{Atipe Emi ko se eda awon alujannu ati awon eniyan (lasan), ayafi ki won le ma sin Mi. * Emi ko fee nkankan lowo won, bee ni Emi ko fe onje. * Dajudaju Olohun ni Olupese, Alagbara ti o le]. (suuratu Adh-dhariyaat:56-58).

O da won, O si pese ohun ti isemi won yio fi rorun fun won, O si ran awon ojise si won, ki won ba semi ni ibamu si bi O se fe, yato si bi awon se fe, ki won ba ma semi ni deede ofin Olohun ati ilana Re ti o yonu si fun won, -Olohun ni o ni apejuwe ti o ga julo- eniyan kan ko le yonu si ki eni kan ma pase fun nibi nkan re, bee naa ni Olohun, ohun ti o ba wu ni yio da ninu awon eda, yio si se ohun ti o ba fe, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَرَبُّكَ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ وَيَخْتَارُ مَا كَانَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ سُبْحَانَ اللَّهِ وَتَعَالَى عَمَّا يُشْرِكُونَ " (القصص:68)

[Oluwa re lo nse eda ohunkohun to ba fe, oun lo si nsa esa, sisa esa ko to si won, mimo fun Olohun, osi ga ju gbogbo ohun ti wo fi nse orogun Re lo]. (Suuratu Al-Qasas:68).

Eleyi ni ero ti a tori re da gbogbo agbaye ati gbogbo ohun ti nbe ninu re, ninu awon agbaye ti a nfi oju ri ati eyi ti a ko ri, ki awon eniyan le se imuse ije eru fun Olohun, ki won si lo gbogbo ohun ti nbe ninu aye lati fi mo Olohun ati lati fi josin fun, (Olohun) ko da won lati gbara le won tabi lati se la nfaani tabi lati le inira lo Fun Un, won ni bukata si, O si roro kuro lodo won, gege bi o se so ninu oro Re pe:

" يَاأَيُّهَا النَّاسُ أَنتُمُ الْفُقَرَاء إِلَى اللَّهِ وَاللَّهُ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ{15} إِن يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ{16} وَمَا ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ بِعَزِيزٍ{17}" (سورة فاطر:15-17)

[Eyin eniyan! Alaini ni eje si Olohun, Olohun si ni Oloro, Oba Olope. * Ti O ba fe yio mu yin lo, yiO si mu eda tuntun wa, atipe iyen ko nira fun Olohun]. (suuratu Al-faatir:15-17).

Eni ba jewo ije eru re bi o se ye, yio jere idekun gbere ti Olohun se ni adehun fun un, eni ti o ba wa je eru fun emi ati ife-inu re, ati esu yio ma be ninu iya gbere ninu ina, Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَالْمُشْرِكِينَ فِي نَارِ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أُوْلَئِكَ هُمْ شَرُّ الْبَرِيَّةِ{6} إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُوْلَئِكَ هُمْ خَيْرُ الْبَرِيَّةِ{7} جَزَاؤُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّاتُ عَدْنٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَداً رَّضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ ذَلِكَ لِمَنْ خَشِيَ رَبَّهُ {8}" (سورة البينة:6-8)

[Dajudaju awon alaigbagbo ninu awon ti a fun ni tira ati awon onsebo yio wa ninu inan jahannama, inu re ni won yio se gbere si, awon ye ni eda ti o buru. Dajudaju awon ti o gbagbo ni ododo, ti won si se rere, awon ye ni eda rere. Esan won ni odo Oluwa won ni awon ogba idera ti won yio wa ninu won titi, ti awon akere-mondo nsan ni abe won, won yio se gbere ninu won lailai, Olohun yio dunnu si won, awon nan won o dunnu si, iye wa fun awon ti o beru Oluwa won]. (Suuratu Al-bayyinah:6-8).

 

Awon ipele (dida) iran eniyan:

 Al-qur'anu salaye ipele dida eniyan, Olohun ti ola Re ga sope:

"الَّذِي أَحْسَنَ كُلَّ شَيْءٍ خَلَقَهُ وَبَدَأَ خَلْقَ الْإِنسَانِ مِن طِينٍ {7} ثُمَّ جَعَلَ نَسْلَهُ مِن سُلَالَةٍ مِّن مَّاء مَّهِينٍ {8} ثُمَّ سَوَّاهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِن رُّوحِهِ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ قَلِيلاً مَّا تَشْكُرُونَ {9}" (سورة السجدة:7-9)

[Eni ti o se gbogbo nkan ti o da eda re daada, ti o si bere eda awon eniyan lati ara amo. * Leyin naa oda awon aromo-domo re lati ara omi logbologbo ti o le. * Leyin naa O se ni dogbandogba, O si fe ninu emi re si i, O si se igboro fun yin ati awon iriran ati awon okan, igba die ni e fi n dupe]. (suuratu As-sajdah:7-9).

Ki se bi awon ti won nso asogbonu se so wipe: (eniyan) je ada kan ti o yipada lati ara eda miran, Olohun ti ola Re ga sope:

 "لَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ فِي أَحْسَنِ تَقْوِيمٍ " (التين: 4)

[Dajudaju, a da eniyan ni eya ti o dara julo]. (suuratu At-teen:4).

 O si se ni ohun ti n yipada lati isesi kan si omiran, ti yio pari pelu sise gbere ninu ogba tabi ninu ina, Al-qur'an royin awon ipele yi ni ona iyanu, ti awon onimimo si kagara lati so iru iroyin yi pelu gbogbo ohun ti won ni ninu mimo, O salaye isemi eniyan pelu gbolohun soki lati ibere re de opin re, eleyi ntoka si jije ododo al-qur'an ati ohun ti o mu wa, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ مِن سُلَالَةٍ مِّن طِينٍ {12} ثُمَّ جَعَلْنَاهُ نُطْفَةً فِي قَرَارٍ مَّكِينٍ {13} ثُمَّ خَلَقْنَا النُّطْفَةَ عَلَقَةً فَخَلَقْنَا الْعَلَقَةَ مُضْغَةً فَخَلَقْنَا الْمُضْغَةَ عِظَاماً فَكَسَوْنَا الْعِظَامَ لَحْماً ثُمَّ أَنشَأْنَاهُ خَلْقاً آخَرَ فَتَبَارَكَ اللَّهُ أَحْسَنُ الْخَالِقِينَ {14} ثُمَّ إِنَّكُمْ بَعْدَ ذَلِكَ لَمَيِّتُونَ {15} ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ تُبْعَثُونَ {16}" (سورة المؤمنون:12-16)

[Dajudaju Awa da eniyan lati inu ipile ti a yo lati inu erupe amo. * Leyin naa A se ni omi logbologbo sinu aye irorun kan. * Leyin naa Awa so omi logbologbo naa di eje didi, leyin na A so eje didi naa di baasi-eran, leyin naa A so baasi-eran naa di eegun, leyin A fi eran bo eegun naa, leyin naa A so di eda miran, ibukun fun Olohun Eni ti O dara julo ninu awon adeda. * Leyin naa dajudaju eyin o ku. * Leyin naa dajudaju won o gbe yin dide ni ojo ajinde]. (suuratu Al-muhmineen:12-16).

 Awon ipele naa niyi:

1- Si so di bibe lati ibi aisi: Omo-eniyan ni ipile o je nkankan, Olohun wa sodi bibe lati ibi aisi, eleyi njuwe agbara Olohun lori igbedide leyin iku, Eni ti O sodi bibe lati ibi aisi kapa ati dapa, koda o rorun fun lati da pada ni igba miran, Olohun ti ola Re ga sope:

 " هَلْ أَتَى عَلَى الْإِنسَانِ حِينٌ مِّنَ الدَّهْرِ لَمْ يَكُن شَيْئاً مَّذْكُوراً {1} إِنَّا خَلَقْنَا الْإِنسَانَ مِن نُّطْفَةٍ أَمْشَاجٍ نَّبْتَلِيهِ فَجَعَلْنَاهُ سَمِيعاً بَصِيراً {2}" ( سورة الإنسان:1-2)

{Dajudaju igba kan ninu awon akoko ti rekoja lori eniyan, ti koje kini Kankan ti a le daruko. * Dajudaju A wa ni A da eniyan lati ara omi gbologbolo ti aropo mon ara won ki A dan wo, A wa se ni olugboro, oluriran]. (suuratu Al-Insaan:1-2).

2- Inu iya: Ninu ipele yi eniyan yio gba awon ipele kan koja titi ti idagba re yio fi pe, ti won yio si fe emi ti yio je ki o mo yipada si, yio wa jade gege bi Olohun se da bi Olohun se salaye ninu (aaya) ti o gbawaju, Olohun ti ola Re ga sope:

"ٍ يَخْلُقُكُمْ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ خَلْقاً مِن بَعْدِ خَلْقٍ فِي ظُلُمَاتٍ ثَلَاثٍ ذَلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ لَهُ الْمُلْكُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ فَأَنَّى تُصْرَفُونَ}" (الزمر: 6)

[O se eda yin si inu ikun awon iya yin ni eda kan leyin dida kan, si inu okunkun meta kan, iye ni Olohun ti o je Oluwa yin, ti E ni ijoba, ko si olohun miran ayafi Oun naa, ki lo se ti e fi nseri (kuro nibi ijosin fun Un)]. (Suuratu Az-zumar:6).

 Olohun ti pese awon nkan ti yio ma mu isemi eniyan seku si inu iya re, boya nipa sise deede aye naa ni eyi ti yio daabo bo (eniyan) nibi ijanba (aburu) ti yio si jeki awon eronja isemi re de odo re, ninu onje tabi nka miran lai lekun tabi dinku, Olohun ti ola Re ga sope:

" أَلَمْ نَخْلُقكُّم مِّن مَّاء مَّهِينٍ {20} فَجَعَلْنَاهُ فِي قَرَارٍ مَّكِينٍ {21} إِلَى قَدَرٍ مَّعْلُومٍ {22} فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ الْقَادِرُونَ {23}" (سورة المرسلات:20-23)

 [Nje a ko ti da yin lati inu omi ti o lagbara (ole)? * Leyin A wa fi si aye kan ti o farabale. * Titi di akoko kan ti a ti mo. * A wa pa ebubu re, Awa ni a dara ju ni olupebubu]. (suuratul mursalaat:20-23).

3- Isemi aye: oun ni ipele Ila (okun esin bo eniyan lorun) ati igbidanwo eni, Olohun da fun eniyan awon nkan igbonmo ti o le muni mo iyato larin ododo ati ibaje, ohun ti o wulo ati ohun ti o le seni nsuta: igboro, irina ati laakai, Olohun ti ola Re ga sope:

"وَاللّهُ أَخْرَجَكُم مِّن بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ لاَ تَعْلَمُونَ شَيْئاً وَجَعَلَ لَكُمُ الْسَّمْعَ وَالأَبْصَارَ وَالأَفْئِدَةَ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ}" (النحل: 78)

[Atipe Olohun mu yin jade lati inu awon iya yin ti e ko mo nkankan, O si se igboro ati awon iriran ati awon okan fun yin, ki e le ma dupe]. (Suuratu An-nahl:78).

O da (eniyan) ni eya ti o dara, O si se nirorun fun ara re ati awon orikerike re sise anfani pelu awon ore aye, O si pese awon orikerike ti yio gbe ara re duro fun, Olohun ti ola Re ga sope:

" أَلَمْ تَرَوْا أَنَّ اللَّهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَأَسْبَغَ عَلَيْكُمْ نِعَمَهُ ظَاهِرَةً وَبَاطِنَةً وَمِنَ النَّاسِ مَن يُجَادِلُ فِي اللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَلَا هُدًى وَلَا كِتَابٍ مُّنِيرٍ " (لقمان: 20)

[E o ripe Olohun je nipa fun yin ohun ti nbe ni sanmo ati ohun ti nbe ni ori-ile, O sip e ike Re leyin lori ni gbangba ati ni koko, o si wa ninu awon eniyan eni ti njiyan nipa Olohun lai ni mimo tabi imonan tabi tira kan ti nse imonle]. (Suuratu luqman:20).

Pelu bo se jepe Olohun ko da won ayafi nitori ijosin re, O tun ran awon Ojise si won, O si so awon tira kale pelu aanu Re, ki won le salaye bi won yio se se ijosin fun Un, ki won si to won sona losi ibi ododo, ki won le tele e, ki won si wa won ni isora kuro ni ibi aburu ki won le jina si, Olohun ti ola Re ga sope:

"{وَمَا نُرْسِلُ الْمُرْسَلِينَ إِلاَّ مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ فَمَنْ آمَنَ وَأَصْلَحَ فَلاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ}" (الأنعام: 48)

[A wa ko ran awon ojise ni ise (nkankan) ayafi ki won je oniro-dunnu, ati olukilo, eni ti o ba gbagbo ti o si se daada, ko ni si iberu fun besini won ko ni banuje]. (Suratu Al An'aam:48).

 Olohun da aye yi fun eniyan ati gbogbo ohun ti nbe nibe, O si roo fun won, ki won le ba ma mu idagbasoke ba pelu idako, igbin nkan, mimo nkan, ati gbogbo ona igbe aye, ki won le gbadun awon nkan wonyi ti won yio si je iranlowo fun won lati sin In, ati lati Mu ni okan soso, Olohun ti ola Re ga sope:

 " هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ ذَلُولاً فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِن رِّزْقِهِ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ " (الملك: 15)

[Oun ni eni ti o se ile fun yin ni riro, nitorinan ki e ma rin ni awon agbegbe re, ki e si ma je ninu ese re, odo Re ni igbedide yio je]. (Suuratu Al mulk:15).

 Ki aye ati gbogbo ohun ti nbe ninu re le je onan irori ati iwoye nipa Oba ti o da, ti yio fi wa leekun ni igbagbo ati igbalododo, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَاخْتِلاَفِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَالْفُلْكِ الَّتِي تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِمَا يَنفَعُ النَّاسَ وَمَا أَنزَلَ اللّهُ مِنَ السَّمَاءِ مِن مَّاء فَأَحْيَا بِهِ الأرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَآبَّةٍ وَتَصْرِيفِ الرِّيَاحِ وَالسَّحَابِ الْمُسَخِّرِ بَيْنَ السَّمَاء وَالأَرْضِ لآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ " (البقرة: 164)

[Dajudaju awon ami ariwoye nbe fun awon oni laakai nibi sise eda sanmo ati ile, ati iyipada oru ati osan, ati awon oko oju-omi ti won ring ere ni inu ibudo pelu ohun ti nse anfaani fun awon eniyan, ati ohun ti Olohun so kale lati sanmo ni omi ojo, ti O si fin ji ile leyin iku re, O si tan awon orisirisi eranko ka si ori re, ati yiyipada ategun, ati esujo ti A jenipa larin sanmo ati ile]. (Suuratu Al-baqorah:164).

 

Awon eri lati inu Al-qur'an lori igbedide ti o ba laakai mu:

Nitoripe oro nipa igbedide leyin iku je ohun ti o ko airoju ba awon eniyan, ti o si mu ki eni ti igbagbo o ti wo inu okan re tako eleyi, idi niyi ti Al-qur'an fi se alaye oro naa, oro naa ki se oro isin yi, ohun ti o ti pe gan ni lati igba ti awon eniyan ti nbe, Olohun ti ola Re ga sope:

" زَعَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَن لَّن يُبْعَثُوا قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ وَذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ " (التغابن:7)

[Awon eni ti won se aigbagbo ro pe won ko nigbe awon dide, sope: bee ni Oluwami ni mo fi bura, dajudaju won o gbe yin dide, won o si fun yin niro ohun ti e se, atipe iye je irorun fun Olohun]. (Suuratu At-taghoobun:7).

 Awon awijare ti awon olutako igbedide nbeere lowo awon Ojise won je ohun ti o le, o si ntoka si igberaga won, ki won wo eda won akoko, Olohun ti ola Re ga sope:

" {وَإِذَا تُتْلَى عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ مَّا كَانَ حُجَّتَهُمْ إِلَّا أَن قَالُوا ائْتُوا بِآبَائِنَا إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ}" (الجاثية: 25)

[Atipe nigba ti a ba ke awon aayah Wa ti o han fun won, awijare won koju ki won sope: emu awon baba wa pada wa, ti e ba je oltito]. (Suuratu Al-Jathiyah:25).

 Nitoripe itako igbedide je ona kan ninu awon ona ti esu mo ngba se royiroyi si eniyan lati seri re kuro nibi igbagbo, o mu ki opo ninu awon Aayah Al-qur'an kanpa mo paapa bibe Olohun ati agbara Re lori igbedide, o wa nse eniyan ni ojukokoro sibi ironu si ipile re, Olohun ti ola Re ga sope:

" ويَقُولُ الْإِنسَانُ أَئِذَا مَا مِتُّ لَسَوْفَ أُخْرَجُ حَيّاً {66} أَوَلَا يَذْكُرُ الْإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن قَبْلُ وَلَمْ يَكُ شَيْئاً {67}" (مريم:66- 67)

[Omo eniyan a ma sope: nje ti mo ba ku, laipe won o tun mu mi jade ni alaaye? Se eniyan ko ranti pe Awa ni A se eda re ni siwaju ki o to je nkan]. (Suuratu Maryam:66-67).

Gege bi o se wa nibi agbekale omo-eniyan nipe: eni ti o ni ikapa lati se nkankan ni ikapa lati sodi nkan miran, - Olohun ni o ni apejuwe ti o ga ju- Oba ti o da eniyan siwaju ki o to je nkankan ni ikapa lati da pada leyin igba ti o je nkan, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَى فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ " (الروم: 27)

[Atipe Oun ni o bere dida eda, leyin naa yio tun da pada, o si rorun fun julo, apejuwe ti o ga julo nbe fun ni sanmo ati ni ile, Oun si ni Alagbara, Ologbon]. (Suuratu Ar ruum:27).

Awon aayah Al-qur'an to fun eni ti o ba gbe sise eleyameya esin ju sile, ti o si lo lakai re, ti o si ba adamo re se, ti nkankan o si ti kolu adamo re. Ninu awon aayah naa ni:

- Eyi ti nso nipa rironu si ipile dida eniyan ni akoko, eni ti o ni ikapa lori ibere nkan, o ni ikapa lati se idapada re leyin aisi re, Olohun ti ola Re ga sope:

" أَوَلَمْ يَرَ الْإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن نُّطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُّبِينٌ {77} وَضَرَبَ لَنَا مَثَلاً وَنَسِيَ خَلْقَهُ قَالَ مَنْ يُحْيِي الْعِظَامَ وَهِيَ رَمِيمٌ {78} قُلْ يُحْيِيهَا الَّذِي أَنشَأَهَا أَوَّلَ مَرَّةٍ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ {79}"( يس:77-79)

[Se eniyan o mo wipe dajudaju Awa ni A da lati ibi (ato), leyin nan o wa je alatako ti o han gbangba. O wa fi apejuwe lele fun wa, o si gbagbe ipile re, o wa sope: tani eni ti yio ji eegun ti o ti ju? Sope: eni ti o se eda re ni akoko ni yio ji dide, Oun si ni Oni-mimo nipa gbogbo eda]. (Suuratu Yasin:77-79).

- Ironu si awon ipele sise eda eniyan, Olohunti ola Re ga sope:

" أيَحْسَبُ الْإِنسَانُ أَن يُتْرَكَ سُدًى {36} أَلَمْ يَكُ نُطْفَةً مِّن مَّنِيٍّ يُمْنَى {37} ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّى {38} فَجَعَلَ مِنْهُ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنثَى {39} أَلَيْسَ ذَلِكَ بِقَادِرٍ عَلَى أَن يُحْيِيَ الْمَوْتَى {40}" (القيامة:36-40)

[Nje eniyan nro pe won o fi oun sile lasan? se koti je omi logbologbo ti won mu jade lati ibi ato? Leyin nan o di eje didi, O si da ni eda ti o pe, O wa mu toko-taya jade nibe ni tako-tabo, nje eni ti o se eyi ko ni agbara lati ye oku]. (Suuratu al-Qiyamoh:36-40).

- Ironu si yiye ile ti o ti ku, pelu irugbin ti Olohun mu jade ninu re, leyin igba ti o ti di (ile)-asale, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَمِنْ آيَاتِهِ أَنَّكَ تَرَى الْأَرْضَ خَاشِعَةً فَإِذَا أَنزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاء اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ إِنَّ الَّذِي أَحْيَاهَا لَمُحْيِي الْمَوْتَى إِنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ " (فصلت: 39)

[Atipe nbe ninu awon ami Re pe dajudaju ire o ri ile ti o tidi asale, nigba ti A ba so omi kale le lori yio gbon yio si gberu, dajudaju eni ti o ye (ile) naa ni yio ye awon oku, dajudaju Oun ni alagbara lori gbogbo nkan].

 (fusilat:39)

 - Ironu nipa agbaye yi ati gbogbo oun ti nbe ninu re, eleyi ti o tobi ju sise eda eniyan lo, eni ti o da a kole kagara lati da isemi pada fun awon oku ti apejuwe won o ju dede era lo ninu gbogbo ohun ti nbe ninu agbanla aye, Olohun ti ola Re ga sope:

" أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَمْ يَعْيَ بِخَلْقِهِنَّ بِقَادِرٍ عَلَى أَنْ يُحْيِيَ الْمَوْتَى بَلَى إِنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ " (الأحقاف: 33 (

[Nje won ko mo pe dajudaju Olohun ti o da sanmo ati ile, ti O si kagara nipa dida won, O ni ikapa lari yiye awon oku, bee ni! Oun ni Alagbara lori gbogbo nkan]. (Suuratu Al- Ahqof:33).

 - Ironu si orun (sisun) eniyan ati itaji re, oun ni iku kekere ti isemi yio si tun gbeyin re, iku omo-eniyan ni iku nla ti isemi yio si gbeyin oun naa, Olohun ti ola Re ga sope:

"اللَّهُ يَتَوَفَّى الْأَنْفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَالَّتِي لَمْ تَمُتْ فِي مَنَامِهَا فَيُمْسِكُ الَّتِي قَضَى عَلَيْهَا الْمَوْتَ وَيُرْسِلُ الْأُخْرَى إِلَى أَجَلٍ مُسَمًّى إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (42) " (الزمر: 42)

[Olohun nmu awon emi lo akoko iku re ati awon ti o ku ni oju orun, yio si mu awon emi ti o pase iku le lori dani, yio si fi awon (emi) miran sile di asiko ti won so, dajudaju ami nbe ninu iye fun awon oni-ronu]. (az zumar:42)

 Leyin naa Olohun tun salaye fun awon olutako ajinde ohun ti yio tobi loju won, oun naa ni agbara Olohun eyi ti nkankan o le di lowo nipa gbigbe awon eda dide leyin iku won ni dede iseju aya, pelu ase kan, lati ori (anobi) adam titi ti aye o fi pare. Dajudaju ti Olohun ba gbero nkankan yio kan pase pe: mo be! Yio si mo be. Olohun ni O ni apejuwe ti o ga julo, iru apejuwe eleyi nbe ninu isemi aye wa ti o ri pe o rorun fun o lati mu imole ba odidi ilu kan latara tite botini ina kan, Olohun ti ola Re ga sope:

" مَّا خَلْقُكُمْ وَلَا بَعْثُكُمْ إِلَّا كَنَفْسٍ وَاحِدَةٍ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ}" (لقمان: 28)

[Dida yin ati gbigbe dide yin ko je nkankan bikose gege bi emi kan soso, dajudaju Olohun ni Olugboro, Olurinan]. (Suratu luqman:28).

 Gbogbo awon aayah Al-qur'an lo wa fun irori, ironu ati awokose, ododo ni Olohun so (ninu oro Re wipe):

" وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ " (القمر: 40)

 [Dajudaju Awa se al quran ni irorun fun iranti, nje ari oluranti]. (Suuratu Al-Qomar:40).

4 isemi inu saare: Oun ni isemi ti gbogbo awon eniyan o to wo leyin iku won. Iku ki se opin isemi awon omo-eniyan, sugbon o je ibere isemi won ni paapa, won o bo si inu isemi miran ti won npe ni isemi (barzakh) inu saare, titi ti Olohun yio fi yonda ki agbaye yi de opin ati gbogbo ohun ti nbe ninu re, nkankan o ni seku ayafi ohun ti Olohun ba fe, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَصَعِقَ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَمَن فِي الْأَرْضِ إِلَّا مَن شَاء اللَّهُ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخْرَى فَإِذَا هُم قِيَامٌ يَنظُرُونَ}" (الزمر: 68)

[Atipe won o fan fere sinu iwo, awon ti won wa ninu sanmo o daku ati awon ti won wa ni ori-ile, ayafi eni ti Olohun ba fe, leyin naa won o tun fan an ni igba miran, igbanan nan ni won o dide ti won o ma wo sun]. (Suuratu Az-zumar:68).

 Ni ipele yi omo-eniyan o je oku ni aye, yio si je alaye ni agbaye miran (ninu saare), ninu ki o ma jiya tabi ki o ma gbadun ni be ni odiwon bi isere re ba se mo. Olohun salaye iyen ninu oro nipa (firiaona) ati awon ijo re, awon ti won pe ise Olohun ni iro ti won si teri (si inu odo):

 " النَّارُ يُعْرَضُونَ عَلَيْهَا غُدُوّاً وَعَشِيّاً وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ أَدْخِلُوا آلَ فِرْعَوْنَ أَشَدَّ الْعَذَابِ " (غافر:46)

[Ina na ni won o seri won si ni owuro ati ni asale, atipe ojo ti akoko naa yio de (won o sope): e fi awon ara firiaona si inu iya ti o le ju]. (Suuratu Al-ghafir:46).

 Leyin naa ni won o fon fere elekeji (fere ajinde), ti yio juwe wipe akoko naa ti to lati gbigbe awon eniyan dide ati sise isiro, awon eniyan o si ma paya fun iberu ohun ti won ngbo ati ohun ti won nri, Olohun ti ola Re ga sope:

" يا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمْ إِنَّ زَلْزَلَةَ السَّاعَةِ شَيْءٌ عَظِيمٌ {1} يَوْمَ تَرَوْنَهَا تَذْهَلُ كُلُّ مُرْضِعَةٍ عَمَّا أَرْضَعَتْ وَتَضَعُ كُلُّ ذَاتِ حَمْلٍ حَمْلَهَا وَتَرَى النَّاسَ سُكَارَى وَمَا هُم بِسُكَارَى وَلَكِنَّ عَذَابَ اللَّهِ شَدِيدٌ {2}" (الحج:1-2)

 [Mope eyin eniyan! E paya Oluwa yin, dajudaju mimi-titi akoko naa je nkan nla, ojo ti e o ri, gbogbo olufunilomu won o gbagbe awon omo ti won nfun lomu, gbogbo awon alaboyun o ma bi oyun won, wa si ri awon eniyan ti won unrira bi eni pe won mu oti, bee sini won o mu oti, sugbon iya Olohun lo le koko]. (Suurau Al-hajj:1-2).

Eto ile aye patapata yio mehe ni akoko naa, orun re, ile re, awon irawo re, Olohun ti ola Re ga sope:

 إِذَا الشَّمْسُ كُوِّرَتْ {1} وَإِذَا النُّجُومُ انكَدَرَتْ {2} وَإِذَا الْجِبَالُ سُيِّرَتْ {3} وَإِذَا الْعِشَارُ عُطِّلَتْ {4} وَإِذَا الْوُحُوشُ حُشِرَتْ {5} وَإِذَا الْبِحَارُ سُجِّرَتْ {6} وَإِذَا النُّفُوسُ زُوِّجَتْ {7} وَإِذَا الْمَوْؤُودَةُ سُئِلَتْ {8} بِأَيِّ ذَنبٍ قُتِلَتْ {9} وَإِذَا الصُّحُفُ نُشِرَتْ {10} وَإِذَا السَّمَاء كُشِطَتْ {11} وَإِذَا الْجَحِيمُ سُعِّرَتْ {12} وَإِذَا الْجَنَّةُ أُزْلِفَتْ {13} عَلِمَتْ نَفْسٌ مَا أَحْضَرَتْ" ( التكوير:1-13)

[Nigba ti won ba ka orun. * Ati nigba ti awon irawo ba njabo. * Ati nigba ti won ba ku oke danu. * Ati nigba ti won ba pa awon aboyun rankunmi ti. * Ati nigba ti won ba ko awon eranko jo. * Ati nigba ti won ba nsun awon ibudo. * Ati nigba ti won ba nso awon emi po mo ara won. * Ati nigba ti won ba bi omobinrin ti won bo mole. * Pe nitori ese wo ni won fi pa. * Ati nigba ti won ba te awon iwe ise kale. * Ati nigba ti won ba jo awon irawo ni ina. * Ati nigbati won ba sun ile idera (al jannah) moni pekipeki. * (Nigba naa) ni emi kokan yio mo ohun ti o se nise]. (Suuratu At-takweer:1-13).

5 - Isiro: Olohun yio gbe awon eda dide, awon eniyan inu won, eye, ati awon eranko, yio wa ko won jo lati se idajo laarin won ni aye ikoraduro ojo ajinde, ki o le se isiro won pelu deede, ko ni se abosi Kankan fun awon eniyan. Olohun ti ola Re ga sope:

" وَنَضَعُ الْمَوَازِينَ الْقِسْطَ لِيَوْمِ الْقِيَامَةِ فَلَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا وَإِنْ كَانَ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِنْ خَرْدَلٍ أَتَيْنَا بِهَا وَكَفَى بِنَا حَاسِبِينَ (47) " (الأنبياء : 47)

[Atipe A o fi awon osunwon ti o se deede lele ni ojo ajinde, ni igba naa won o ni se abosi fun emi kankan, ti ise ba kere gegebu horo irugbin (khardal) A o mu jade, Awa to ni Oluse-isiro]. (Suratu Al-anbiyaai: 47).

 Won o se isiro gbogbo ijo kookan pelu ofin ohun ti Olohun se lo fin lori ahan awon ojise won, won o san onigbagbo ododo ni esan daada, won o si je opuro niya, Olohun ti ola Re ga sope:

" يَوْمَ نَدْعُو كُلَّ أُنَاسٍ بِإِمَامِهِمْ فَمَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ فَأُولَئِكَ يَقْرَءُونَ كِتَابَهُمْ وَلَا يُظْلَمُونَ فَتِيلًا (71) وَمَنْ كَانَ فِي هَذِهِ أَعْمَى فَهُوَ فِي الْآخِرَةِ أَعْمَى وَأَضَلُّ سَبِيلًا (72) " (الإسراء: 71-72)

[Ni ojo ti A o pe gbogbo awon eniyan pelu awon asiwaju won, nigbanan, eni ti won ba fun ni tira re pelu owo otun re, awon un ni won o ka tira won, won ko ni se abosi fun won botilewu ki o mo, eni ti o ba je afoju ni aye yi (ti ko ri ododo), eni nan yio je afoju ni ojo ikeyin, yio si sonu tefetefe]. (Suuratu Al-Israai:71-72).

 Leyin naa won o wa gbesan larin awon eda gege bi ojise Olohun Anobi Muhammad (ki ike ati ola Olohun maa ba) se salaye re ninu oro re pe:

[Nje e mo eni ti o sofo? Won sope: eni ti o sofo ninu wa ni eni ti o ni owo (diram) Kankan ko si ni nkan anfani Kankan. O wa sope: olofo ninu awon ijo mi ni eni ti yio wa pelu irun, awe, ati saka ni ojo ajinde, yio si de leni ti o bu eleyi, o ti puro agbere mo eleyi, o ti je owo eleyi (ni ije ibaje) o ti ta eje eleyi sile, o ti fi iya je eleyi, won o wa fun eleyi ninu daada re, won o fun eleyi naa ninu daada re, ti daada re bawa tan siwaju ki won to pari adajo re, won o mu ninu asise won, won o si jon mo asise re, leyin naa won o ba ju si inu ina]. (Saheeh Muslim).

Ninu deede Olohun, Oba mimo ti ola Re ga, ni wipe awon eranko gba esan laarin ara won, idi niyi ti won fi pe ojo naa ni ojo isiro. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun maa ba) sope:

 [Tulasi egbodo da awon iwo pada fun awon ti won ni i, koda won o gba esan fun ewure ti o ni iwo lowo oni'wo ti o kan an" (Saheeh Muslim).

 Nigba ti won ba pari gbigbesan larin awon daba tan, Olohun yio so fun won pe: e di erupe. Ni igbanaa ni alaigbagbo yio ma sope: o ma se fun mi o!!! ki emi naa si di erupe, ni igba ti o ba ri pe oun o le moribo nibi iparun, Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّا أَنذَرْنَاكُمْ عَذَاباً قَرِيباً يَوْمَ يَنظُرُ الْمَرْءُ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ وَيَقُولُ الْكَافِرُ يَا لَيْتَنِي كُنتُ تُرَاباً" (النبأ: 40 (

{Dajudaju Awa ni Akilo iya ti o sunmo fun yin, ojo ti eniyan yio ri ohun ti owo re ti siwaju, alaigbagbo yio si sope: o ma se fun mi o!!! ki nsi je erupe}. (Suuratu An-Nabai:40).

Leyin naa ni awon eniyan a fonka si ona meji ti kosi iketa fun un- ile idera (Al-Jannah) ati tabi ina ti joni geregere, won o ma be nibe gbere, eleyi ni ofo fun awon opuro eni anu. Nitori eleyi, ki awon olusise ma se ise won lo, ki awon oluronu si ronu jinle, Olohun ti ola re ga sope:

" وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يَوْمَئِذٍ يَتَفَرَّقُونَ [14] فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَهُمْ فِي رَوْضَةٍ يُحْبَرُونَ [15] وَأَمَّا الَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَلِقَاءِ الْآخِرَةِ فَأُولَئِكَ فِي الْعَذَابِ مُحْضَرُونَ [16}" [الروم: 14- 16].

{Atipe ojo ti akoko naa o de ni ojo naa won o fonka. * E o ri awon ti won gbagbo ti won si se ise rere won o ma jegbadun ninu abata. * E o ri awon ti won ko ti won si pe awon aami Wa niro ati ojo ikeyin, awon wonyi ni won o muwa si inu iya}. (Suurat Ar-ruum:14-16).

6- Ile ikeyin: Awon olugbagbo ododo ti won gba awon ojise won gbo, ti won si lo awon asiko won pelu itele ti Olohun, ti won si tele awon ase Re, ti won si jina si awon ewo Re, won o ma be ninu ogba idera oni idera gbere, eyi ti ohun ti oju o ri ri nbe ninu re, ati ohun ti eti o gbo ri, ati ohun ti ko ru wuye ri ninu okan eda kan, ninu orire ati idunu gbere ati isemi lailai, gege bi Olohun ti ola Re ga se royin re wipe:

 " لَهُمْ فِيهَا مَا يَشَاؤُونَ خَالِدِينَ كَانَ عَلَى رَبِّكَ وَعْداً مَسْؤُولاً {16}" (الفرقان:16)

{Ohun ti won fe nbe fun won ninu re, ti won o se gbere (ni be), o je adehun ti won o bere lowo Oluwa re}. (Suuratu Al-Furqon:16).

Won o ma je ninu re, won o si ma mu, won o ni tuto, won o ni yagbe, beni won o ni fonkun, ohun ti won ba je tabi mu yio ma jade ni ara won pelu gigunfe ati lilaagun ti yio dabi orun (almisiki), ko si aisan ninu re, olupepe kan yio ma pe won wipe: alaafia yio ma je ti yin, e o si ni saisan lailai, isemi yio ma je ti yin, e o ni ku lailai, ewe yio ma je ti yin e o ni dogbo lailai, igbadun yio ma je ti yin e o ni mo inira lailai, gege bi Ojise Olohun se salaye re ( ike ati ola Olohun ko ma ba).

 Sugbon awon alaigbagbo, olujiyan, ati awon olupe awon Ojise Olohun niro ati ohun ti won mu wa, won o ma be ninu ina, won o se gbere ninu re, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقْضَى عَلَيْهِمْ فَيَمُوتُوا وَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمْ مِنْ عَذَابِهَا كَذَلِكَ نَجْزِي كُلَّ كَفُورٍ (36) وَهُمْ يَصْطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَا أَخْرِجْنَا نَعْمَلْ صَالِحًا غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ أَوَلَمْ نُعَمِّرْكُمْ مَا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَنْ تَذَكَّرَ وَجَاءَكُمُ النَّذِيرُ فَذُوقُوا فَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ نَصِيرٍ (37) " (فاطر: 36-37)

{Atipe awon ti won saigbagbo ina (jahannamo) yio ma be fun won, won o ni pa won depo ti won o ku, won o si ni se iya re ni fufuye fun won, beni won o se san gbogbo awon alaigbagbo lesan. * Won o ma pariwo ninu re wipe: Ire Oluwa wa mu wa jade a o se ise rere, yato si eyi ti ase seyin, nje A o ni ki emi yin gun se dede asiko ti eni bafe ronu le fi ronu? Olukilo si wa bayin, e to (iya) wo, kosi oluranlowo kankan fun awon alabosi}. (Suuratu Al-faatir:36-37).

Won o ma be ninu iya gbere ti koni ja, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُواْ بِآيَاتِنَا سَوْفَ نُصْلِيهِمْ نَاراً كُلَّمَا نَضِجَتْ جُلُودُهُمْ بَدَّلْنَاهُمْ جُلُوداً غَيْرَهَا لِيَذُوقُواْ الْعَذَابَ إِنَّ اللّهَ كَانَ عَزِيزاً حَكِيماً}" (النساء: 56)

{Dajudaju awon ti won se aigbagbo awon aami wa, A o fi ina jo won, nigbakigba ti awon awo won ba jin, A o paro awon awo miran fun won, ki won le to iya wo, dajudaju Olohun je Alagbara, Ologbon}. (Suuratu An-nisai:56).

Onje won ni igi egun (doreeh) ti o buru jai, Olohun ti ola Re ga sope:

"لَّيْسَ لَهُمْ طَعَامٌ إِلاَّ مِن ضَرِيعٍ لا يُسْمِنُ وَلا يُغْنِي مِن جُوعٍ" (الغاشية: 6)

{ko si onje kankan fun won ayafi igi egun (doreeh) ko ni yo won, ko si ro won loro kuro nibi ebi]. (Suuratu Al- ghashiyah:6).

Ati igi (zaqoom), Oun ni igi kan ti yio hu lati isalesale ina (jaheem), ti ekikan kan ba kan si awon ara aye yio ba isemi won je, Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّ شَجَرَةَ الزَّقُّومِ طَعَامُ الأَثِيمِ كَالْمُهْلِ يَغْلِي فِي الْبُطُونِ كَغَلْيِ الْحَمِيمِ" (الدخان: 43-46)

{Dajudaju igi (zaqoom) ni onje awon elese gege bi epo gbigba ni yio ma ho ninu, gege bi omo gbigbona se ma nho". (Suuratu Ad-dukhan:43-46)

Ati awonuweje: (oun ni awon omi ati oogun ti njade lara awon ero ina), Olohun ti ola Re ga sope:

"فَلَيْسَ لَهُ الْيَوْمَ هَاهُنَا حَمِيمٌ وَلا طَعَامٌ إِلاَّ مِنْ غِسْلِينٍ لا يَأْكُلُهُ إِلاَّ الْخَاطِؤُونَ" [الحاقة: 35-37]

{Ko si ore timotimo fun un ni ojo na, ko si si onje fun un ayafi awonuweje, eni kan o ni je ayafi awon alasise}. (Suuratu Al-haaqoh:35-37).

Nkan mimu won ni omigbona, won o fi jo ikun won ati awo won, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَسُقُوا مَاء حَمِيمًا فَقَطَّعَ أَمْعَاءهُمْ " (محمد: 15)

{Won o fun won ni omigbona mu, yio sige awon ifun won}. (Suuratu Muhammad:15).

 Ewu won ni oso ti won da fun ara won lati ibi ina, gegebi Olohun ti ola Re ga se salaye re ninu oro Re pe:

" فالَّذِينَ كَفَرُوا قُطِّعَتْ لَهُمْ ثِيَابٌ مِّن نَّارٍ يُصَبُّ مِن فَوْقِ رُؤُوسِهِمُ الْحَمِيمُ {19} يُصْهَرُ بِهِ مَا فِي بُطُونِهِمْ وَالْجُلُودُ {20} وَلَهُم مَّقَامِعُ مِنْ حَدِيدٍ {21} كُلَّمَا أَرَادُوا أَن يَخْرُجُوا مِنْهَا مِنْ غَمٍّ أُعِيدُوا فِيهَا وَذُوقُوا عَذَابَ الْحَرِيقِ {22}" ( الحج:19-22)

 {Awon ti won se aigbagbo won o ge aso fun won lati ara ina, won o si ma da omigbona lati oke ori won * Won o fi jo iku won ati awo won * Atipe oduro onirin si nbe fun won, * Gbogbo igba ti won ba fe jade ninu re nitori ibanuje ni won o ma da won pada sinu re, e to iya ina jonijoni je}. (Suuratu Al-hajj:19-22).

Ibiyi ni isemi gidi yio ti bere, ni ile ti yio seku ti yio si se gbere, ko ni si iku. Ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ige fun un) sope: [Ti awon ara ile idera (aljannah) ba wo inu aljannah, ti awon ara ina naaa si wo inu ina, olupepe kan yio pepe pe eyin ara aljannah e ma se gbere ninu re kosi iku fun yin, eyin ara ina e ma se gbere ninu re kosi iku fun yin] (Al-bukhaari).

Eniyan ti o ba je onilaakai yio ma palemo fun ojo na, yio si bere si ni se isiro ara re, se ori oju ona ti o to ni oun wa tabi bee ko? Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّ اللّهَ لاَ يَظْلِمُ النَّاسَ شَيْئاً وَلَـكِنَّ النَّاسَ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ " (يونس: 44)

{Dajudaju Olohun ko ni se abosi kankan fun omo-eniyan, sugbon awon eniyan ara won ni won nse abosi si}. (Suuratu yunus:44).

 

 

 

Wiwa bukata eda si Olohun ti yio ma sin:

Awon eniyan ni bukata si olujosin fun kan ti emi won o ma teriba fun un, gege bi ara won se ni bukata si awon nkan isemi ti yio gbe duro, ninu jije ati mimu, bee na ni awon emi won ni bukata si Eleda kan ti won o ma josin fun, ti won si ma bere awon bukata won lodo Re, ti won o ma yepere ara won fun un, ki won le ri ifokanbale ni abe re, omo-eniyan ti koje eru fun Olohun da gege bi awon eranko ti ko si ironu kankan fun won ayafi abe ati inu won, eleyi ni kan to ni apejuwe fun anu won ati aironu jinle won, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّ اللَّهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الْأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ " (محمد:12)

{Dajudaju Olohun yio fi awon ti won gbagbo lododo ti won si se ise rere wo inu ile idera (aljannah) ti akeremodo nsan ni abe re, awon ti won si ko o ma gbadun, won o ma je gege bi awon eranko se nje, inu inan ni ibudesi won} (Suuratu Muhammad:12).

Lai si (ije eru fun Olohun) omo-eniyan o ma be bi eranko, alagbara yio ma se abosi fun ole, oloro ninu won o si ma je owo talika ni ije ibaje, won o ni se ike omo kekere inu won, bee ni won o ni bowo agbalagba, won o ni ran ole ati alaisan lowo, isemi won yio je isemi ima wa awon nkan anfani ati ije- imu lasan.

Won se adamo emi omo-eniyan ni ohun ti o gbafa fun bibe Adeda re, ati Aseda agbaye yi, ti yio ma josin fun, eleyi ni awon onimimo npe ni (adamo ti t'esin), Olohun ti ola Re ga sope:

 " فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا فِطْرَتَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللَّهِ ذَلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ (30) " (الروم:30(

{Gbe oju re duro fun esin mimo- kanga, (oun ni) adamo ti Olohun da awon eniyan le lori, kosi iyipada fun eda Olohun, iye ni esin ti o duro deede, sugbon opo ninu awon eniyan won o mo} (Suuratu Ar-ruum:30).

Ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola Re fun un) sope: [kosi omo kan ayafi ki won bi si ori adamo-ipile, sugbon awon obi re mejeeji ni won o sodi yahudi tabi nasara (elesin kirisi) tabi aborisa]. (Al-bukhaari).

Koda ti adamo awon omo-eniyan ba yi pada kuro nibi adamo re ti Olohun da won le lori, wa ri adamo yi ti yio ma wa agbara kan ti yio ma ba gbo bukata re, ti yio si ma kepe ni asiko ifunpinpin ati isoro, apejuwe eleyi wa lara awon ijo ti oti gbawaju, won ma nmu olohun miran yala lati ibi awon irawo, awon igi tabi awon okuta, adamo yi nbe fun gbogbo awon eniyan patapata lai si ayokuro, sugbon nbe ninu won eni ti ntako o pelu igberaga, o si nbe ninu won eni ti o fi rinle ti o si ni igbagbo pelu e, adamo yio si ma han nigba ti adanwo ba de, bi aisan tabi isoro, wa ri eniyan ni asiko naa ti yio ma sope: ire Olohun o! tabi ki o gbe oju re soke leni ti n wo sanmo, eleyi tumo si ijewo pe nkankan wa ti o ni agbara lati yo kuro ninu adanwo naa. Ododo ni Olohun so ni igba ti O so pe:

" وَإِذَا مَسَّ النَّاسَ ضُرٌّ دَعَوْا رَبَّهُم مُّنِيبِينَ إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا أَذَاقَهُم مِّنْهُ رَحْمَةً إِذَا فَرِيقٌ مِّنْهُم بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ {33}" (الروم:33)

{Nigba ti inira ba gba awon eniyan mu won o pe Oluwa won, ti won gbafa fun, leyin nan ti aanu ba towon wo lati odo Re nigba naa ni awon apakan ninu won o ma se ebo pelu Oluwa won}. (Suuratu Ar-ruum:33).

Bakanna, nigba ti inira ati ibanuje ba de ododo yio han, iro ninu awon ti won josin fun leyin Olohun yio foju han gedegbe, sise afomo adua fun Olohun ododo yio sele, Oba ti ikapa gbogbo nkan nbe lowo Re, ti o si ni ikapa lati sipaya inira. Al-qur'an se alaye eleyi pe:

" وَإِذَا مَسَّ الْإِنْسَانَ الضُّرُّ دَعَانَا لِجَنْبِهِ أَوْ قَاعِدًا أَوْ قَائِمًا فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُ ضُرَّهُ مَرَّ كَأَنْ لَمْ يَدْعُنَا إِلَى ضُرٍّ مَسَّهُ " (يونس: 13)

{Nigba ti inira ba gba eniyan mu yio ma pe Wa ni isunle tabi ni ijoko tabi ni iduro, ti A ba ti mu inira lo fun yio rekoja bi pe ko pe Wa fun inira ti o gba mu}. (Suuratu yunus:13).

Tabi nigba ti ohun ti ko nife si ba yo sii lojiji, ko ni ri alagbaale kan yato si agbara ti o pamo yi, eyi ti yio ni igbonmo re pe o nbe, o si ni agbara lati ko oun yo, Olohun ti ola Re ga sope:

 "{هُوَ الَّذِي يُسَيِّرُكُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ حَتَّى إِذَا كُنتُمْ فِي الْفُلْكِ وَجَرَيْنَ بِهِم بِرِيحٍ طَيِّبَةٍ وَفَرِحُواْ بِهَا جَاءتْهَا رِيحٌ عَاصِفٌ وَجَاءهُمُ الْمَوْجُ مِن كُلِّ مَكَانٍ وَظَنُّواْ أَنَّهُمْ أُحِيطَ بِهِمْ دَعَوُاْ اللّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ لَئِنْ أَنجَيْتَنَا مِنْ هَـذِهِ لَنَكُونَنِّ مِنَ الشَّاكِرِينَ}" (يونس: 22)

{Oun (Olohun) ni nmu yin rin ni oke odan ati ninu odo, koda nigba ti e ba nbe ninu oko oju-omi, ti ngbe won lo pelu ategun ti o dara, ti inu won si n dun pelu re, ti ategun agan kan wa de wa ba won, ti igbi-odo si wa ba won ni gbogbo aye, ti won ro wipe owo ti te awon, won o wa pe Olohun ni Oun nikan: ti O ba yo wa ninu eleyi a o ma be ninu awon oludupe}. (Suuratu yunus:22).

Awon ijo ti o ti saaju ma n mu awon orisa ni olohun won yato si Olohun ododo, latari adamo ijosin ti Olohun da awon eniyan mo, nigba ti awon esin (ti won mu wa lati sanmo) pamo si won, esin alaafia ti yio yo adamo ije eru won, bayi ni adamo omo-eniyan yi se bere si ni wa olujosinfun ti yio yo, won ba ndamu, won si sonu, won si olujosinfun ninu eda Olohun bi ti won, ododo ni Olohun so, pe:

" إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ عِبَادٌ أَمْثَالُكُمْ فَادْعُوهُمْ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ} (الأعراف: 194(

{Dajudaju, awon ti e sin yato si Olohun erusin bi ti yin ni won, e pe won ki won jepe yin ti e ba je olododo}. (Suuratu al-A'roof:194).

O seni laanu pe laakai ti o ni alaafia tako awon olujosinfun yi, bi awon okuta, awon igi, awon irawo, awon eranko, awon abe ati beebe lo, koda adamo ti o ni alaafia gan tako pelu, ninu ohun ti o ko ibanuje bani ni pe awon ti won sin awon nkan wonyi eleko giga ni won, olaju si ni won, awon ilu ti imo won si poju ni won gbe awon iru ijosin yi dani. Ododo ni Olohun so:

"يَعْلَمُونَ ظَاهِراً مِّنَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ الْآخِرَةِ هُمْ غَافِلُونَ" (الروم: 7 (

{Won mo tifun-tedo nipa isemi aye, won si je afonu-fora nipa ojo ikeyin}. (Suuratu Ar- ruum:7).

Sayyid Qutub (ki Olohun se ike fun un) sope: " Awon eniyan o ni ikapa lati semi lai se ijosin kankan! Tulaasi ni fun won ki won se ijosin, awon ti won o josin fun Olohun won o ko si inu aburu ijosin fun orisirisi nkan ti o yato si Olohun, ni gbogbo agbegbe isemi won, won o ko si inu panpe ife inu won ati awon ojukokoro won lai si ala ati onde fun, won o wa se afeku ije omo Anobi adam won, won o si kosi inu agbaye eranko, Olohun ti ola Re ga sope:

 ‏"وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الْأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوًى لَهُمْ"‏ ‏(‏محمد‏:12).‏

{Awon alaigbagbo o ma gbadun, won o si ma jehun gege bi awon eranko se njehun, inu inan si ni ibudesi won}. (Suuratu Muhammad:12).

Kosi ofo kan ti o to ki eniyan se ofo ije omo anobi adam re, ki o si bosi inu agbaye awon eranko, eleyi ni yio sele si i ti o ba fi ijosin fun Olohun nikan sile, ti yio si kosi inu ijosin fun ife emi re ati ojukokoro re, yio si ma josin fun orisirisi nkan ninu awon eda Olohun, gege bi awon adajo ati awon olori ti won o ma dari won pelu awon ofin ti won gbe kale fun ara won, ko si onde (fun awon ofin yi) kosi si afojusun kan yato si idaabo bo awon anfaani awon asofin, yala ofin aladani ni tabi ti gbogbogbo, eleyi foju han kedere nibi gbogbo ofin ti won o mu wa lati odo Olohun nikan, ti kosi ni abase kankan pelu ofin Olohun.

Eleyi yio je ki a mo pataki ijosin fun Olohun nikan soso nibi siso emi awon eniyan ati nkan-ini won, ati omoluwabi won, ti kosi nkan ti o le so nigba ti eru ba ti njosin fun erusin egbe re, ni eyikiyi ona ti nba gba sin, yala lona ofin esin sise ni tabi ofin iseda awujo, tabi nipa adiokan.

 

Awon eri lati inu laakai lori ije okan soso Olohun:

Oko oju-omi yio ma teri nigba ti awon atokun re ba je meji, ile-ise yio mehe ti o ba ni oludari meji, ofo yio sele si owo sise ti ase re ba nbe lowo eniyan meji, ekinni-keji won yio fe jegaba bori enikeji re, kini a o wa so nipa agbaye ti o fe yi, ti irawo kan ba mehe ninu awon irawo be yio wo lule, yio si faya, ti o ba je pe awon olohun mi wa yato so Olohun ni ifanfan ti yio ba nkan je ko ba sele. Ododo ni Olohun so nigba ti O sope:

 " لَوْ كَانَ فِيهِمَا آلِهَةٌ إِلَّا اللَّهُ لَفَسَدَتَا فَسُبْحَانَ اللَّهِ رَبِّ الْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ}" (الأنبياء: 22)

{Ti o ba je pe awon olohun miran wa yato si Olohun ni (sanmo ati ile) ko ba baje, mimo fun Olohun Oluwa (aga- alarashi) nibi gbogbo ohun ti won fi nroyin Re}. (Suuratu Al-anbiyaa:22).

 Ninu adamo awon akegbe ati awon orogun ni ki won ma se ifanfa larin ara won lati jegaba lori ara won, nitori ki ipase le wa fun ikinikeji won, eleyi si ma nfa aseti nibi ise ati aini aseyori. Olohun ti ola Re ga sope:

" مَا اتَّخَذَ اللَّهُ مِن وَلَدٍ وَمَا كَانَ مَعَهُ مِنْ إِلَهٍ إِذاً لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَهٍ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلَا بَعْضُهُمْ عَلَى بَعْضٍ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ}" (المؤمنون: 91(

{Olohun ko ni omo Kankan, ko si si olohun miran pelu Re, ti o ba ri bee ni olohun kookan ko ba mu nkan to seda sodo, apakan won ko ba si joba lori apakan, mimo fun Olohun nibi gbogbo ohun ti won fi nroyin Re}. (Suuratu Al-mu'minuun:91).

Tabi bi awon oba aye se ma n se ifanfa lari ara won, ti won si ma nba ara won ja, ikookan ninu won yio ma fe sisubu ijoba enikeji, yio si fe ki ijoba je ti e nikan, Olohun ti ola Re ga sope:

 " قُل لَّوْ كَانَ مَعَهُ آلِهَةٌ كَمَا يَقُولُونَ إِذاً لاَّبْتَغَوْاْ إِلَى ذِي الْعَرْشِ سَبِيلاً}" (الإسراء: 42)

{Sope: ti o ba jepe olohun miran wa pelu Re ni gege bi won se nso, nigbana, won ba wa onan lati (gba ijoba lowo Olohun) Oba ti o ni aga-alarashi}. (Suuratu Alisraa:42).

 Sayyid qutub (ki Olohun se ike fun un) so nipa oro Olohun ti o so pe:

 " مَا اتَّخَذَ اللَّهُ مِن وَلَدٍ وَمَا كَانَ مَعَهُ مِنْ إِلَهٍ "

"Olohun ko ni omo kankan, ko si si olohun miran pelu Re" Leyinna (Olohun) tun mu eri ti yio pe apemora won ni iro wa, O si salaye iro ati airorun ti n be nibi mimu orogun pelu Olohun,

 "إِذاً لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَهٍ بِمَا خَلَقَ"

 " Ti o ba ri bee ni olohun kookan ko ba mu nkan to seda sodo", ko ba da duro pelu ohun ti o da, yio ma dari re ni ibami si eto ti e loto, ti yio yato gedegede si eto awon elomiran,

"وَلَعَلَا بَعْضُهُمْ عَلَى بَعْضٍ"

 "Apakan won ko ba si joba lori apakan" pelu pe ki agbara re ati ofin bori agbaye ti ko le seku ko si le ma lo letoleto ayafi pelu ofin kan, eto kan, amojuto kan, ko si nkankan lagbaye ninu awon ona ti a salaye yi, ije okan soso dida agbaye yi ntoka si okan soso Aseda re, ije okan soso ofin re ntoka si okan soso Alamojuto re, gbogbo ida nkan ti o wa ninu re, gbogbo nkan si se regi ninu re, lai si afikunlukun kan tabi ifanfa, tabi gbonmisi-omioto…

"سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ}"

 "mimon fun Olohun nibi gbogbo ohun ti won fi nroyin Re")

 

 

Ije eru ninu islam:

 Islam ni esin awon Anobi Olohun ati awon Ojise Re, nitoripe paapa igbafa fun Olohun ati ijuwo-juse le Fun Un pelu titele E ati imowo-mose kuro nibi mimu orogun pelu Re je ipo ti o ga julo, bi o ba se se ije eru re fun Olohun to naa ni wa fi ri ominira to, bi o ba se teriba Fun Un to naa ni wa fi ri iyi to, bi o ba se yonu Si to naa ni wa ri ifokanbale ati isinmi to, Olohun se ni iyi fun awon Anobi Re ati awon Ojise Re lapapo, latori Anobi nuh (ike Olohun ki o ma ba) ti o fi dori igbeyin won Anobi Muhammad (ki Olohun se ike ati ige fun). Olohun ti ola Re ga sope:

"وَلَقَدْ سَبَقَتْ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا الْمُرْسَلِينَ {171} إِنَّهُمْ لَهُمُ الْمَنصُورُونَ {172} وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ الْغَالِبُونَ {173}" ( الصافات: 171-173)

{Dajudaju, oro Wa ti gbawaju fun awon erusin Wa ti won je ojise, wipe dajudaju, awon ni eni ti A ran lowo, atipe dajudaju, awon omo-ogun Wa ni olubori" (Suuratu As-soffaat:171-173).

Ije eru fun Olohun ni ofin esin gbogbo awon Ojise, won o ran won ayafi ki won le pataki re, Olohun ti ola Re ga nba Ojise Re Anobi Muhammad (ki Olohun se ike ati ige fun) soro pe:

 " شَرَعَ لَكُم مِّنَ الدِّينِ مَا وَصَّى بِهِ نُوحاً وَالَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ وَمَا وَصَّيْنَا بِهِ إِبْرَاهِيمَ وَمُوسَى وَعِيسَى أَنْ أَقِيمُوا الدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُوا فِيهِ كَبُرَ عَلَى الْمُشْرِكِينَ مَا تَدْعُوهُمْ إِلَيْهِ اللَّهُ يَجْتَبِي إِلَيْهِ مَن يَشَاءُ وَيَهْدِي إِلَيْهِ مَن يُنِيبُ {13}" (الشورى:13)

{O se lofin fun yin ninu esin iru ohun ti so asokale re fun anobi nuha, ati eyi ti A fi ranse si o, ati ohun ti A so asokale re fun anobi musa, ati anobi isa, pe ki e gbe esin duro daada, ki e si ma fonka yeleyele ninu re, ohun ti o npe awon onsebo si o soro fun won, Olohun ma nsa eni ti o ba fe lesa wasi odo Re, osi ma nfi onan mo eni ti o ba seri wa sodo Re} (Suuratu Ash-shura:13).

Ninu ohun ti ntoka si titobi (ije eru fun Olohun) ni bibe Anobi (ike ati ola Olohun ki o maa ba) fun odun metala ni makkah leyin igba ti won gbe dide lojise ti npe awon eniyan losi ibi mimo pataki ije eru fun Olohun nikan, ati sise atunse awon adisokan won ti o ti kuro ni ojuwon re, bi sisin orisa, o ma nlo si aye ijoko won ati awon aye ipejo won ti yio ma so fun won pe: "mope eyin eniyan!!! Eso pe ko si olujosinfun miran lododo yato si Olohun (ti e ba so bee) e o jere" (Saheeh Ibn Hibban, ati Saheeh As-siratu-n-nabawiyyah).

Nitoripe ije eru fun Olohun ni opo ofin esin ti awon ofin ati ise oranyan ma ti ara re dide, lai si (ije eru fun Olohun) gbogbo awon ise oranyan, ofin, ise asegbore, ati awon ise ti a fi nsun Oluwa wa ma je asedanu ti won ko si ni jamo nkankan gege bi Olohun se salaye eleyi fun Ojise Re Muhammad (ike ati ola Olohun ki o maa ba) pe:

"وَلَقَدْ أُوحِيَ إِلَيْكَ وَإِلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكَ لَئِنْ أَشْرَكْتَ لَيَحْبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ الْخَاسِرِينَ * بَلِ اللَّهَ فَاعْبُدْ وَكُنْ مِنَ الشَّاكِرِينَ" (الزمر 65: 66).

{Dajudaju, won ti ranse si o, ati si awon ti won gbawaju re, (pe) ti o ba sebo ise re yio baje, wa si ma be ninu awon eni-ofo. * Sugbon Olohun ni ki o sin, ki o si ma be ninu awon oludupe}. (Suuratu Az-zumar:65-66).

Eleyi ni ilana Ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ige fun un) ati ilana awon saabe re nigba ti o ran won lati pepe ati lati fon esin Olohun ka, o ma pa won lase ki akoko ipepe won je ipepe losi ibi mimo paapa ije eru fun Olohun nikan, o so fun mu'adh omo jabal (ki Olohun yonu sii) nigba ti o gbe dide losi ilu yaman: "dajudaju wa lo baa won ijo kan ninu awon ara onitira, ti o ba de odo won pe won pe ki won jeri pe kosi olujosinfun lododo ayafi Olohun, atipe anobi Muhammad ojise Olohun ni se, ti won ba tele o ni bi iye, so fun won pe Olohun se awon irun wakati marun kan lorayon le won lori lojoojumo, ti won ba tele o nibi iye, sofu won pe Olohun se saka yiyo loranyon le won lori, won o gba lowo awon oloro ninu won fun awon talika ninu won, ti won ba tele o nibi iye, awon ojulowo nkan ini won dowo re, si beru epe eni ti won se abosi fun nitoripe kosi gaga laarin re ati Olohun". (Al-bukhaari)

 Olohun ti ola Re ga pa wa lase ki a sin oun nikan, ki a si jawo kuro nibi eyikiyi ije eru fun elomiran, ki ife-inu wa si se dede ohun ti O pawa lase re ti o si se ni ofin fun wa ninu oro aye ati ti ojo ikeyin, ti kii se ni ibamu si ohun ti awon eda se fun ara won, pelu ijawo yi ni enikookan o fi se atunse larin oun ati emi re, Olohun ti ola Re ga sope:

" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ اتَّقُواْ اللّهَ وَكُونُواْ مَعَ الصَّادِقِينَ " (التوبة :119)

{Mope eyin olugbagbo ododo! E beru Olohun, ki e si ma be pelu awon olododo}. (Suuratu At-taoba:119).

Ti enikookan yio tun se atunse laari oun ati awujo re, Ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ige fun) sope: "e gbo o! e je ki n fun yin ni iro nipa olugbagbo ododo, oun ni eni ti awon eniyan fi okan bale si lori awon nkan ini won ati awon emi won, musulumi ni eni ti awon eniyan la nibi ahan re ati owo re, jagunjagun ni eni ti o ja emi re logun sibi itele ti Olohun, oni irinajo-esin ni eni ti o gbe awon asise jusile ati awon ese". (Imam Ahmad ni o gba wa)

 Ije eru fun Olohun pelu gbogbo ohun ti o tumo si ninu ase Olohun ati awon eewo Re E ma nko ojukoko awon eniyan ti yio ko iparun ba aye ati gbogbo ohun ti n be ninu re, yala eleyi ti o ni ohun se pelu omo-eniyan ni, Olohun ti ola Re ga sope:

" يأَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا يَسْخَرْ قَومٌ مِّن قَوْمٍ عَسَى أَن يَكُونُوا خَيْراً مِّنْهُمْ وَلَا نِسَاء مِّن نِّسَاء عَسَى أَن يَكُنَّ خَيْراً مِّنْهُنَّ وَلَا تَلْمِزُوا أَنفُسَكُمْ وَلَا تَنَابَزُوا بِالْأَلْقَابِ بِئْسَ الاِسْمُ الْفُسُوقُ بَعْدَ الْإِيمَانِ وَمَن لَّمْ يَتُبْ فَأُوْلَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ {11} يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيراً مِّنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ وَلَا تَجَسَّسُوا وَلَا يَغْتَب بَّعْضُكُم بَعْضاً أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَن يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتاً فَكَرِهْتُمُوهُ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَّحِيمٌ {12}" ( الحجرات:11-12)

{Mope eyin ti e gbagbo ni ododo! Ijo kan ko gbodo fi ijo kan se yeye, o see se ki won loore juwon lo, awon obinrin o gbodo fi awon obinrin se yeye, o see se ki won loore ju won lo, e ma bu ara yin, e ma dara yin pe pelu adape buruku, oruko ti ko dara buru leyin igbagbo, eni ti ko ba tuba awon ni alabosi. * Mope eyin ti e gbagbo lododo! E jinnan si opo ninu aba-dida, dajudaju apakan ninu aba ese ni, e ma se ofintoto, apakan yin o gbodo soro apakan leyin (laida), se o wu enikan ninu yi ki o ma je oku-nbete omo iya re, bee ni ekorira re! e beru Olohun, dajudaju, Olohun ni Alamojukuro, Onike}. (Suuratu Al-hujuraat:11-12).

 Tabi eyi ti o ni ohun se pelu akojo, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَاعْبُدُواْ اللّهَ وَلاَ تُشْرِكُواْ بِهِ شَيْئاً وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً وَبِذِي الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينِ وَالْجَارِ ذِي الْقُرْبَى وَالْجَارِ الْجُنُبِ وَالصَّاحِبِ بِالجَنبِ وَابْنِ السَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ إِنَّ اللّهَ لاَ يُحِبُّ مَن كَانَ مُخْتَالاً فَخُوراً}" (النساء: 36)

{ki e si maa sin Olohun, ki e si ma pa nkankan po moo, ki e si maa se rere si awon obi mejeeji, ati awon ebi, ati awon omo-orukan, ati awon alaini, ati awon aladugbo ti o sunmo yin, ati awon aladugbo ti o jinnan, ati awon ore alabarin, ati omo-ojuonan, ati awon ti owo otun yin ni (ni akapa), Olohun ko fe awon onigberaga, onifaari}. (suuratu An-nisaai:36).

Tabi eyi ti o ni ohun se pelu awujo, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَلاَ تُفْسِدُواْ فِي الأَرْضِ بَعْدَ إِصْلاَحِهَا وَادْعُوهُ خَوْفاً وَطَمَعاً إِنَّ رَحْمَتَ اللّهِ قَرِيبٌ مِّنَ الْمُحْسِنِينَ" (الأعراف: 56)

{E ma se ibaje lori ile leyin atunse re, ki e si pe (Olohun) pelu iberu ati afokansi, dajudaju, aanu Olohun sunmo oluse daada}. (Suuratu Al-A'roof:56).

Tabi eyi ti o ni ohun se pelu isejoba: Olohun ti ola Re ga sope:

 " {لَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ أَن تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ" (الممتحنة: 8(

{Olohun ko ko fun yin - kuro lodo awon ti won ko bayin ja ninu esin, ti won ko si le yin jade kuro ni awon ile yin - lati se daada si won, ati lati se deede pelu won, dajudaju, Olohun nife awon olusedeede}. (Suuratu Almumtahinah:8).

 Tabi n ti o ni ohun se pelu eto-isuwonan, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَلاَ تَأْكُلُواْ أَمْوَالَكُم بَيْنَكُم بِالْبَاطِلِ وَتُدْلُواْ بِهَا إِلَى الْحُكَّامِ لِتَأْكُلُواْ فَرِيقاً مِّنْ أَمْوَالِ النَّاسِ بِالإِثْمِ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ" (البقرة: 188)

{Ema je owo yin laarin ara yin ni ije ibaje, ti e fi wa gbe lo odo awon adajo ki e fi le je ipin kan ninu awon owo awon eniyan pelu ese, ti eyin si mo bee}. (Suuratu Al baqorah:188).

Ti a ba woye pelu lakai wa ti ki se pelu igbenu wa, a o mo amodaju pe dajudaju pelu ije eru fun Olohun ni isemi omo-eniyan yio fi gunrege. On pepe losi ibi siso agbaye yi latara siso awon ohun ti yio so siseku re di irorun ati bibe re. Kofi aye gba gbogbo ohun ti o le ko iparun ba enikookan tabi awujo re, tabi ile ati awon ohun ti n be nibe. O je ilana fifon awon iwa alaponle ka gege bi ojise Olohun se so pe: "dajudaju, won gbemi dide lati pe awon iwa alaponle". (Al-bukhaari).

Bakanna, o tun je ona fifon ife kaakiri, ati aanu, alaafia, deede, imototo, ida afokantan pada, pipe adeun, titore awon orisirisi nkan daada, - fun aladugbo, ati alaini, ati onirin-ajo, ati onibukata - sise pelepele, sise rere si awon obi mejeeji, dida ebi po, sise irorun, ini ife daada si enikeji, ati bee bee lo, ki se eleyi nikan koda ti o fi dori sise daada si awon eranko, o je ipin kan ninu awon ona ijosin fun Olohun, gege bi ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun ) se so pe: "esan n be nibi (sise daada) si gbogbo nkan ti o ni edo tutu (ti n semi)".

Ati ijina si awon iwa ti ko dara, ati sise leewo gbogbo ohun ti o le jeki aburu fonka ni awujo, gege bi abosi, ole jija, iro, itanje, kiko awon ohun isemi ni awujo pamo, owo-ele, iyapa obi mejeeji, pipa emi ti a se leewo, jije owo omo-orukan, agbere, asepo larin okunrin s'okunrin, eri eke, yiyapa adeun, jija okun ebi, owo oya, ina apa, idi osunwon ku, motomoto, oro-eyin, ofofo, adapa iro, ati bee bee lo, ninu awon ise tabi oro tabi iwa buruku ti o ma nba eto awujo je, ti o si ma nle ifokanbale jina, Olohun ti ola Re ga sope:

 " قُلْ تَعَالَوْاْ أَتْلُ مَا حَرَّمَ رَبُّكُمْ عَلَيْكُمْ أَلاَّ تُشْرِكُواْ بِهِ شَيْئاً وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً وَلاَ تَقْتُلُواْ أَوْلاَدَكُم مِّنْ إمْلاَقٍ نَّحْنُ نَرْزُقُكُمْ وَإِيَّاهُمْ وَلاَ تَقْرَبُواْ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَلاَ تَقْتُلُواْ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللّهُ إِلاَّ بِالْحَقِّ ذَلِكُمْ وَصَّاكُمْ بِهِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ {151} وَلاَ تَقْرَبُواْ مَالَ الْيَتِيمِ إِلاَّ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ حَتَّى يَبْلُغَ أَشُدَّهُ وَأَوْفُواْ الْكَيْلَ وَالْمِيزَانَ بِالْقِسْطِ لاَ نُكَلِّفُ نَفْساً إِلاَّ وُسْعَهَا وَإِذَا قُلْتُمْ فَاعْدِلُواْ وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَى وَبِعَهْدِ اللّهِ أَوْفُواْ ذَلِكُمْ وَصَّاكُم بِهِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ {152}"( الأنعام:151-152)

{Sope: ewa kin so ohun ti Oluwa yin se leewo leyin lori, e ma mun orogun Kankan pelu Re, ki e si se daada si awon obi mejeeji, e ma pa awon omo yin nitori osi, Awa ni A n se ije-imu fun yin ati awon nan, e ma sunmo awon ohun ti ko dara, eyi ti o han ninu re tabi ti o pamo, e ma pa emi ti Olohun se leewo ayafi pelu onan eto, iye ni O so asokale re fun ki e le se lakaye. E ma sunmo owo omo-orukanayafi ni onan ti o dara, titi ti yio fi balaga, e won kobiowu pe, ati osunwon pelu deede, A o la nkankan bo emi kan lorun ayafi ki o ni agbara re, ti e ba soro e se deede koda ki o je larin awon monlebi, e pe adeun Olohun, iye ni o so asokale re fun yin ki e le ranti}. (Suuratu Al-An'aam:151-152)

Eleyi ni iranse ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) ti o fi de ori eni ti o se aida si i, ti o mu jade kuro ni ilu re, ti o gbiyanju lati se iku pa, amojukuro ati pelepele ni ilana re ti o se alaye re fun awon saabe re, nigba ti won wa lodo re ki o sepe le awon onsebo ti won se won ni suta, ti won si le won jade kuro ni ilu won, won si se afihan lile won jade, o wa sope: " Won ko gbemi dide ni elepe, sugbon dajudaju won gbemi dide ni ike". (Muslim)

Ije eru ninu Islam ko mo lori awon ijosin nikan, bi irun, saka, awe ati ohun ti o ba jo won, bi ki sepe oun ni igbafa fun Olohun ati ijuwojuse le fun Un ati ijepe re, nibi sise awon ohun ti O pa lase, ati jijina si ohun ti o se leewo, ati ima dari gbogbo ijosin si odo Re, nitoripe Oun ni o ni pipe ponbele ti ko ni adinku kankan ni gbogbo ona pelu pe ki gbogbo ijosin je ti E nikan, O so nipa ara Re pe:

 " لَيْسَ كَمِثْلِهِ شَيْءٌ وَهُوَ السَّمِيعُ البَصِيرُ " (الشورى: 11)

{Kosi nkankan bi iru Re, Oun ni Olugboro, Oluriran}. (Suuratu Ash-shuura:11).

Awon nkankaan wa ti o tako paapa ije eru Fun Un, eru yio jade kuro nibi iroyin ije eru fun Un losi ibi ije eru fun nkan miran, ko le je musulumi koda ki o mo pe apemora Islam, gege bi idan pipa, iye ise wo, iwa alubarika pelu saare awon eniire, ati igi, ati awon okuta, ati riruku ati ifori kanle ati irokirika awon nkan wonyi, ati fifi awon nkan rubo ati ebun fun awon saare, ti won si gbee tobi ni ero wipe awon ara re je eni rere, won le se anfani fun un beni won le fi inira kan won, o si nbe ninu awon ise yi ohun ti o le ko abuku ba ijosin, ti yio je ki musulumi maa be ninu ewu lori esin re, gege bi dide nkan mo ara (irin, okun, owu ati bee bee lo) lati ti aburu nu tabi daa pada, ati gbigbe paro ko orun nitori ati so ara eni kuro ni ibi aburu aje. Eleyi lomu ki ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun un) kilo to po nipa awon isesi bayi, o sope: "e gbo o!!! dajudaju, awon ti won nbe siwaju yin maa nmu sare awon anobi won ni aye iforikanle, e gbo o! e ma mu awon sare ni aye iforikanle, dajudaju emi nko fun yin". (Muslim).

 Ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) si maa npa awon saabe re lase ki won fi oun si aye ti Olohun fi oun si, ki won si ma se aseju nibi gbigbe e tobi tabi fifomo, nitori iberu ki awon ijo re ma kosi inu ohun ti awon ijo ti o siwaju kosi, o sope: " e ma yin mi ni eyin ayinju gege bi awon elesin kirisi (nasara) se yin isa omo maryam ni eyin ayinju, dajudaju, emi je eru, e sope eru Olohun ati ojise Re". (Al-bukhaari).

 Shaykh Abu bateen sope: "gbogbo esin patapata o pari si ibi ijosin, ti eniyan ba mo amodaju itumo ti o wa fun gbolohun (Ilaha) Olujosin fun, ti o si mo paapa ijosin, yio han si gedegbe pe eni ba gbe nkankan ninu ijosin fun nkan miran yato si Olohun, ti o si mu ni olohun, koda ki o sa lati pe ni olujosinfun tabi olohun, yiyi oruko pada ko le yi paapa nkan pada, kosi le mu idajo re kuro, (nigbati adiyyu omo hatim wa sodo ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) nigbana o je elesin kiristeni, o gbo ti n ka aayah yi:

 "اتَّخَذُوا أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ وَالْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا إِلَهًا وَاحِدًا لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ سُبْحَانَهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ" (التوبة:31)

{Won mu awon adari won ati awon asiwaju won ati (moseeh) isa omo moryam ni oluwa yato si Olohun, won ko pawon lase ayafi ki won josin fun Olohun kan soso, kosi olohun miran ayafi oun nan, mimo fun un kuro nibi gbogbo ohun ti (won nsin pelu Re)}. (Suuratu At-taobah:31).

O sope: mo wa so fun pe: dajudaju awa kii josin fun won, o sope: se won kii se nkan ti Olohun se leewo ni eto ti eyin naa o si se ni eewo? Won kii se nkan ti Olohun se ni eto ni eewo ti eyin naa o si se ni eewo? O sope: mo sope: bee ni, o sope: " Iye naa ni ijosin fun won". (Al-bukhaari).

Ti o ba jepe enikan wa ti o ni agbara sise ni lanfaani tabi dida inira pada ni awon ojise Olohun ni o ba je ati awon anobi Re, sugbon awon nkan wonyi owo Olohun ni o wa. Ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) ti mowomose kuro nibi ete re ati agbara re lori mimu anfaani wa tabi dida inira pada fun ara re, Olohun ti ola Re ga sope:

" قُل لاَّ أَمْلِكُ لِنَفْسِي نَفْعاً وَلاَ ضَرّاً إِلاَّ مَا شَاء اللّهُ وَلَوْ كُنتُ أَعْلَمُ الْغَيْبَ لاَسْتَكْثَرْتُ مِنَ الْخَيْرِ وَمَا مَسَّنِيَ السُّوءُ إِنْ أَنَاْ إِلاَّ نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ}" (الأعراف: 188(

{Sope: mi o ni agbara sise anfaani fun ara mi ati dida inira pada ayafi ohun ti Olohun ba fe, ti o jepe mo ba mo koko ni mi o ba ni ore, aburu o si ni kan mi, mi o je nkankan tayo olukilo olufu awon ijo ti won gbagbo lododo ni iro-idunnu}. (Suuratu Al-A'roof:188).

 Bakanna, o mowomose kuro nibi ete re ati agbara re lori mimu anfaani wa tabi dida inira pada fun elomiran, Olohun ti ola Re ga sope:

" قلْ إِنَّمَا أَدْعُو رَبِّي وَلَا أُشْرِكُ بِهِ أَحَداً {20} قُلْ إِنِّي لَا أَمْلِكُ لَكُمْ ضَرّاً وَلَا رَشَداً {21} قُلْ إِنِّي لَن يُجِيرَنِي مِنَ اللَّهِ أَحَدٌ وَلَنْ أَجِدَ مِن دُونِهِ مُلْتَحَداً {22}" ( الجن:20-22)

{Sope: dajudaju, mo npe Oluwa mi, mi o si ni mu nkankan pelu Re. * Sope: dajudaju, mi o ni agbara lati fi inira kan yin tabi toyin sona. * Sope: dajudaju, enikan o le gba mi lowo Olohun, mi o si ni elomiran yato Sii ti mo le lo saba}. (Suuratu Al-jinn:20-22).

Bawo ni oro alfa wa Sayyid Al-Qutub se dara to nigba ti o sope: " I mo josin fun elomiran yato si Olohun ninu adisokan ati iwoye tumo si iko si inu ero buruku ati adapa iro ti ko ni opin, eleyi ti aimokan awon elebo se dede eya kan ninu re, irori orisirisi awon eniyan ti a ko naani ni awujo naa se dede awon eya kan ninu re, bi ki won mo se ileri tabi pa nkan ninu nkan ini tabi omo, gbogbo e pata ninu adiokan ti ko dara ni ati iwoye ti o ti tase agere. Awon eniyan si n semi pelu biberu awon oluwa agbelero won yi, ati awon oluso ati awon adifa ti won ni ajose pelu awon oluwa won yi, ati awon opidan ti won ni ajose pelu awon aljannu, ati ninu awon agba afa ati awon eni mimo ti won je alasiri, ati bee bee lo ninu awon nkan ti awon eniyan nberu, ti won n sunmo, ti won n se agbokante lodo won, ti won ndamu lori won".

Ije eru fun Olohun ma nrun iwonkoko ojukokoro ti o dabi ti eranko jegejege, yio si da pada sibi adami re ti Olohun gba lero, yio ma wa se ile lemi, yio si so agbayi yi kuro nibi fifi awon nkan ti n be ninu re sere, ti oripa awon nkan yi si ti nhan ni ori ile, bi imo ijinle nipa awowo sanmo ati gbigbona ile, ati ohun ti o ba joo, lati ara afokansi awon eniyan ati ijina si ije eru fun Olohun ni won fi n se ibaje ti won pee ni ominira, won si ra awon iwo lare ti won npe ni olaju, won je owo awon eniyan ni ije ibaje won npe ni owo oni-ominira, won mu awon eniyan leru ti won pe ni ofin aladani, jijuraenilo ti o buru wa gbajumo ni awujo ati eleyameya, ebo wa gbale ati jijosin fun orisa. Ododo ni Olohun so bayi pe:

" ظَهَرَ الْفَسَادُ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ بِمَا كَسَبَتْ أَيْدِي النَّاسِ لِيُذِيقَهُم بَعْضَ الَّذِي عَمِلُوا لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ " (الروم: 41)

{Ibaje han ni oke odan ati ninu ibudo latara ohun ti awon eniyan fi owo won fa, ki O le fi iya apakan ohun ti won se je won, ki won si le seri pada}. (Suuratu Ar-ruum:41).

Sayyid Al-Qutub (ki Olohun ke e) sope: "Dajudaju, ijosin fun Olohun ma ntu eniyan sile nibi ijosin fun nkan miran, yio si mu eniyan jade kuro nibi sisin eda losi ibi sisin Olohun nikan, iyen ni yio je ki eniyan ri paapa aponle re ati ominira re, a o le ri eleyi ayafi ninu Islam, ti a ko le ri ninu ofin kankan ti apakan awon awon eniyan wonyii yio ma josin fun ara won ni ona ti o po, boya nipa adisokan tabi nipa ilana, tabi nipa ofin, gbogbo e pata n tumo si ijosin, ti won si jo ara won, awon orun nteriba fun nkan ti o yato si Olohun pelu gbigbafa fun itele awon ilana yi ninu isemi.

Nigbati ije eru ba je ti nkan ti o yato si Olohun ni agbaye olaju, ofin awon eniyan ko le so awon ole ninu won, isemi eranko ti agbara yio maa je dukia ole, oloro yio si maa yepere talika, yio lo awon orisirisi ona nipa mimo se ofintoto awon asise, ki o le je gaba lori awon dukia koda ki o je pelu didi ona orire elomiran tabi ki o gba isemi re, sugbon ije eru fun Olohun ki ra awon iwo lare, koda o tun ma nso iwo awon ole ati awon agbalagba, ki ra awon iwo won lare, koda awon ni won leto si ki won so omoluwabi won, ati dukia won, awon olukeni Olohun yio se ike fun won, e se ike awon ti nbe ni ori-ile, Eni ti nbe ni sanmo yio se ike yin, eleyi ni ohun ti ije eru fun Olohun fi mo musulumi.

Islam de lati tu okun eru kuro ni orun eniyan, oun ni o koko seni loju kokoro lori re, o se ni okunfa iha opolopo awon ese ti won n da danu, o sise ofin iranlowo fun eni ti o ba fe ra ara re kuro ninu okun eru. Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَالَّذِينَ يَبْتَغُونَ الْكِتَابَ مِمَّا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ فَكَاتِبُوهُمْ إِنْ عَلِمْتُمْ فِيهِمْ خَيْراً وَآتُوهُم مِّن مَّالِ اللَّهِ الَّذِي آتَاكُمْ " (النور:33)

{Awon ti won nfe akosile (lati ra ara won) ninu awon ti e mu leru, e ko akosile fun won ti e ba mo daada mo won, e fun won ninu owo Olohun ti O fun yin}. (Suuratu An-noor:33).

 Bee ni o wa lati tu okan eniyan sile nibi jije eru fun elomiran yato si Olohun, ati fifi ara ti odo elomiran yato si Olohun, o so won kuro nibi awon iro agbelero, opidan ati adifa, pelu ohun ti o gbin si won lo kan nipa gbigbafa pe inira ati anfaani owo Olohun lo wa, ohun ti O ba fe yio se, ohun ti ko ba fe ko ni se, atipe gbogbo awon eniyan patapata abe ipase Re ni won wa ati fife Re, Olohun ti ola Re ga sope:

 " مَا أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ وَمَن يُؤْمِن بِاللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ {11}" ( التغابن:11)

{Adanwo kan ko le sele ayafi pelu iyonda Olohun, eni ti o ba ni igbagbo nipa Olohun Yio fi okan re monan, Olohun ni imo nipa gbogbo nkan}. (Suuratu At-taghaabun:11).

Awon eniyan ju ara won lo nipa jije eru fun Olohun, yio ma sele si won ohun ti o ma nsele si awon elomiran nitoripe eniyan ni won, bi ki awon ojukokoro bori won, ati awon ohun ti emi nfe, won ki se malaika, won ki se eni ti won so kuro nibi asise.

Alfa wa Ibn Al-qoyyim sope: "ije eru je ikan ninu ohun adani fun Olohun, eyi ti o duro lori origun meji, ko le duro laisi mejeeji: ogongo ife ati ogongo iyepere, eleyi ni ije eru ti o pe, awon eda o maa ju ara won lo ni be niwoye si bi won ba se ju ara won lo nibi awon ipile mejeeji yi, eni ti o ba fi ife re ati iyepere re fun nkan miran yato si Olohun, o ti fi se afiwe Re nibi adani iwo Re, eleyi ko seese ki ofin kan muu wa ninu awon ofin, ninu nkan adani Olohun ni iforikanle, eni ti o ba fi ori kanle fun nkan miran o ti se afiwe eda pelu Re, ninu re ni igbaraleni, eni ti o ba gbara le nkan miran o ti se afiwe Re pelu nkan naa, ninu re ni ituba, eni ti o ba seri tituba losi odo nkan miran o ti se afiwe Re pelu nkan naa". (Al-Jawaabul-Kaafi).

Ajose taara laarin eru ati Oluwa re:

Ije eru fun Olohun ma ngbe emi ga, yio si tu sile kuro nibi ije eru fun nkan miran yato si Olohun, yio je ki ajosepo taara ma a be laarin awon eniyan ati Eleda won, ko ni si alagata larin Re ati laarin won, oju ona Re si wa ni sisi ni gbogbo igba, gbogbo aye ati ni gbogbo isesi, ko si oluso ni oju ona Re, ti won o ma mu eni ti o ba wu won wole, ti won o si ma ko fun eni ti o ba wu won, iwo naa bo si ojuona Re ki ogbe bukata re si odo Re, pariwo ohun ti o fe sodo Re ki o wa iranlowo Re fun ohun ti o nfe, bere gbogbo ohun ti o fe ti n se kulukulu ninu okan re, dajudaju ore Re kosi opin fun un, gege bi Olohun ti ola Re ga se sope:

" وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌ أُجِيبُ دَعْوَةَ الدَّاعِ إِذَا دَعَانِ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لِي وَلْيُؤْمِنُواْ بِي لَعَلَّهُمْ يَرْشُدُونَ " (البقرة:186)

{Ti awon erusin Mi ba bere lowo re nipa Mi, dajudaju Emi sunmo, Mo ma n jepe ipepe olupepe ti o ba pe Mi, ki o jepe Mi, ki o si ni igbagbo nipa Mi, ki won le je olumona}. (Suuratu Al-baqorah:186).

 Bi o ti wu ki ese re po to, bi o ti wu ki o se aseju to nibi ese, o ni bukata si alarina larin Re ati iwo lati wa aforijin, asepo larin iwo ati Oba ti n be ni sanmo wa ni sisi kale, ohun ti o ku ni ki o je olododo pelu Olohun ati sise afomo ise pelu Re, Olohun ti ola Re ga sope:

 "ومَن يَعْمَلْ سُوءاً أَوْ يَظْلِمْ نَفْسَهُ ثُمَّ يَسْتَغْفِرِ اللّهَ يَجِدِ اللّهَ غَفُوراً رَّحِيماً {110}"(النساء:110)

{Eni ti o ba se aburu tabi ti o se abosi fun ara re, leyinan, ti o wa aforijin lodo Olohun, yio ri Olohun ni Alaforijin, Onike}. (Suuratu An-nisaai:110).

Bo ti wu ki bukata re po to, ki ohun ti o nfe tobi to, inu Re a ma dun lati gbo adura re, ati titoro bukata re lodo Re, ati irababa re ni iwaju Re, Olohun ti ola Re ga sope:

" {ادْعُواْ رَبَّكُمْ تَضَرُّعاً وَخُفْيَةً إِنَّهُ لاَ يُحِبُّ الْمُعْتَدِينَ}" (الأعراف: 55)

{Epe Oluwa yin pelu irababa ati koko, dajudaju, ko ni ife si olukojala}. (Suuratu Al-A'roof:55).

Pepe oro Re ko le tan, ore Re ko le dopin, ko si eni ti o le da ola Re pada, ko si si eni ti o le ko ore Re fun ni. Olohun ti ola Re ga so ninu hadeeth (alqudusi) mimo pe "eyin erusin Mi! mo se abosi leewo fun ara Mi, mo si see leewo, e ma sese abosi, mope eyin erusin Mi! dajudaju eyin nda ese ni oru ati ni osan, Emi si nse aforijin gbogbo ese, Mi o bikita, e wa aforijin lodo Mi, Maa forijin yin, mope eyin erusin Mi! gbogbo yin ni elebi ayafi eni ti Mo ba fun ni onje, e wa onje lodo Mi, Maa fun yin ni onje, mope eyin erusin Mi, e o le fi inira kan Mi, bee ni e o le se Mi ni anfaani, mope eyin erusin Mi! ti o ba je wipe eni akoko ninu yin, eni igbeyin ninu yin, alujonnu ninu yin ati eniyan ninu yin ba kojo, ti okan won wa da gegebi okan eni ti o ya poki ju ninu yin, iyen ko di nkankan ku ti o se dede omona igun ninu ola Mi, ti o ba je wipe eni akoko ninu yin, eni igbeyin ninu yin, alujonnu ninu yin ati eniyan ninu yin ba kojo si aye kan, ti gbogbo won si bere nkan lowo Mi, ti Mo si fun enikookan won ni ibere re, iyen ko din nkankan ku ninu ohun ti n be ni odo Mi, ayafi bi abere se ma ndin omi akedo ku nigba ti won ba ki bo inu re, mope eyin erusin Mi! dajudaju awon ise yin niyi ti won nda pada fun yin, eni ti o ba ri daada ki o dupe fun Mi, eni ti o ba ri idakeji ki o ma bu enikankan ayafi ara re" (Muslim)

 Olujosinfun lododo ko ni bukata si alagata laarin Re ati awon eru Re, O mo won, O mo isesi won, On gbo oro won, O mo koko won ati ipamo won, opo ibeere awon eda Re ko le ko idamu ba a, ti oun ti bose jepe awon ede won ati awon ibeere won yato si ara won, ko ni bukata si eni kan ti yio maa gbe bukata awon eda Re wasi odo Re, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ}" (غافر: 60)

{Oluwa yin sope: e pe Mi, Maa dayin lohun, dajudaju, awon ti won se motomoto lati pe Mi, won o wo ina (jahannam) ni eni yepere}. (Suuratu Al-ghafir:60).

 Eleyi ni ohun ti Oba mimo to ola Re ga salaye fun awon eru Re, ki won le sora fun danadana ti won fe maa be larin Olohun ati awon eda Re, Olohun ti ola Re ga sope:

" أَلَا لِلَّهِ الدِّينُ الْخَالِصُ وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِهِ أَوْلِيَاء مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللَّهِ زُلْفَى إِنَّ اللَّهَ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ فِي مَا هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي مَنْ هُوَ كَاذِبٌ كَفَّارٌ " (الزمر: 3)

{E gbo o! ti Olohun ni esin ti o mo kanga, awon ti won mu elomiran ni ayo (ti won nso pe a ko sin won ayafi ki won le sun wa mo Olohun ni ipo, dajudaju Olohun yio dajo laarin won nibi ohun ti won nse iyapa eni ni be, dajudaju, Olohun ko ni fi onan mo opuro, alaigbagbo}. (Suuratu Az-zumar:3).

 

 

Awon abajade sise ijosin fun nkan miran yato si Olohun:

Dajudaju gbogbo ohun ti oju awon awujo agbaye nri, yala abuleko ni tabi ilu nla, ninu awon orisirisi abosi awujo, opinya molebi, fifonka iwa ti ko dara, imura ninu mimu nkan oloro, sise idari ni ona ti kodara, iloseyin eto isuwona ati oselu ati ohun ti a nri ninu awon ogun ati iparun ni agbaye loni, oka ninu ohun ti o fa ni ijina si paapa ije eru fun Olohun, eyi ti npase gbogbo daada, ti o si nko kuro nibi gbogbo nkan ti ko dara ati aburu. Ododo ni Olohun Oba nla so pe:

 " وَلَوِ اتَّبَعَ الْحَقُّ أَهْوَاءهُمْ لَفَسَدَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ وَمَن فِيهِنَّ بَلْ أَتَيْنَاهُم بِذِكْرِهِمْ فَهُمْ عَن ذِكْرِهِم مُّعْرِضُونَ " (المؤمنون:71)

{Ti o ba je pe (Olohun) fi ododo si ibi ife-inu won ni awon sanmo ati ile ko ba baje ati ohun ti n be ninu won, sugbon A fun won ni iranti won, won je olugunri kuro nibi iranti won}. (Suuratu Al-mu'minun:71).

Ki won le mo pe iju ara eni lo nbe nibi paapa ije eru fun Olohun, bi awon enikookan ninu awujo ba ti njina si ije eru fun Olohun to naa ni won o maa bosi inu iyepere, ati anu, bi won ba se se paapa ije eru fun Olohun si ni won o jina si iyepere to, awujo won o si dara ati awon nasa. Olohun ti ola ga sope:

 " فَمَنِ اتَّبَعَ هُدَايَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشْقَى (123) وَمَنْ أَعْرَضَ عَنْ ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنْكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَى (124) قَالَ رَبِّ لِمَ حَشَرْتَنِي أَعْمَى وَقَدْ كُنْتُ بَصِيرًا (125) "(طه: 123).

{Eni ti o ba tele imona Mi ko ni sonu ko si ni soriburuku * Eni ti o seri kuro nibi iranti Mi, dajudaju, isemi ifun pinpin yio maa be fun, A o si gbe dide ni ojo ajinde ni afoju * Yio sope: Oluwa mi! nitori kinni O fi gbemi dide ni afoju ti mosi ti je olurinan tele}. (Suuratu Toha:123).

Sayyid Al-Qutub (ki Olohun se ike re) sope: "o sele pe awon ti won ba ije eru won fun Olohun nikan je, ti won fi aye gba elomiran ninu won ki o maa dajo fun won pelu ofin miran yato si ofin Olohun, ni igbeyin won kosi inu oriburuku ije eru fun elomiran, ije eru ti yio ba omoluwabi won je, bi o ti le wu ki ofin ti ndari won ri, eyi ti won rope yio daabo bo ije eniyan won ati omoluwabi won. Awon ara ilu alawo funfun sa kuro lodo Olohun nigba ti won sa kuro ni soosi (ile ijosin won) ti o je ile abosi ile ikoja ala, won so pe esin agbelero ni, won jade si Olohun, nigbati ti won jade si soosi (ile ijosin) naa, eyi ti o ko iparun ba iwo awon omo-eniyan ni asiko ti agbara abosi nbe ni owo re, leyin naa awon eniyan ro pe awon o ri ije omo-eniyan won, ominira won, aponle won ati awon anfani won nibi awon ofin ijoba aladani ti (demokiresi), nigba ti won so gbogbo ero won mo wiwa ominira ati awon nkan adani eyi ti ofin agbelero yio muwa fun won ati afowosowopo ijoko awon agbaagba, ati ominira ilu iwe, ati awon anfani idajo pelu titi ofin yio fi rinle fun won, ati idajo ti won o gbe lori ife opo eniyan ti yio ni abayori daada, ati orisirisi awon iwuri ti ofin naa kosi inu….., leyin naa ki lo je ikangun re? ikangun re naa ni ibaje ti o ko iparun ba awon nkan anfani yi, ti o di ohun igbagbe ati ala oju-orun, opolopo ninu awon eniyan wa di eru yepere fun awon ijo kan ti won je alabosi, ti won gbese le ojulowo nkan awon eniyan, won gbegi le apanupo ijoko awon iko asofin, ati awon ofin agbelero, ati ominira ti iwe iroyin, ati awon orisirisi anfani ti awon eniyan lero pe yio je ti won, ti yio je ki won ri omoluwabi won, aponle won ati ominira won, eyi ti won ko ri lodo Olohun Oba mimo".

Leyin naa ni awon apakan ninu awon eniyan sa kuro nibi ofin aladani losi ibi ofin gbogboogbo, ki ni won se? won paaro idaja ijoba ti o gbe ola fun idari isuna aladani pelu ijoba ti o gbe ola fun idari ohun isuna ati ohun oro ilu ni ibamusi ijoba apaapo ilu, ti eleyi si buru ju ijoba ti o gbe ola fun idari dukia ilu nibamusi adani enikookan. Ni gbogbo ona ati ofin ti eniyan ba ti n sin eniyan egbe re ni won o maa san owo ori tasi dipo dukia won ati emi won, won o maa san fun awon orisirisi oluwa won ni gbogbo ona.

 

 

 

Abawole si inu ije paapa eru fun Olohun

Dajudaju ogidi abawole sibi ije paapa eru ni aimu orogun pelu Olohun nipa bibe Re, awon oruko Re, awon iroyin Re, awon ase Re ati awon eewo Re, ki gbogbo isemi re se deede ohun ti Olohun nfe, nitoripe won mo ije eru pa lori ife, iteriba ati itele. Olohun ti ola Re ga sope:

" قُلْ إِنَّ صَلاَتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ}" (الأنعام: 162)

{Sope: dajudaju irun mi, pipa eran mi, isemi mi ati iku mi ti Olohun ni, Oluwa gbogbo agbaye}. (Suurtau Al-An'am:162)

 Ti a ba se afeku okan ninu won, ije eru ko le je tooto, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَمِنَ النَّاسِ مَن يَتَّخِذُ مِن دُونِ اللّهِ أَندَاداً يُحِبُّونَهُمْ كَحُبِّ اللّهِ وَالَّذِينَ آمَنُواْ أَشَدُّ حُبّاً لِّلّهِ وَلَوْ يَرَى الَّذِينَ ظَلَمُواْ إِذْ يَرَوْنَ الْعَذَابَ أَنَّ الْقُوَّةَ لِلّهِ جَمِيعاً وَأَنَّ اللّهَ شَدِيدُ الْعَذَابِ " (البقرة: 165)

{O wa ninu awon eniyan awon ti won o maa mu orogun pelu Olohun, won o ma nife won iru ife ti o ye ki won ni si Olohun, awon ti won je olugbagbo ododo ni ife won poju si Olohun, ti o ba je pe awon alabosi ba mo (iru iya ti yio je won) ni igba ti won o ri iya, won o ba mo pe dajudaju Olohun ni O ni gbogbo agbara atipe dajudaju Olohun le koko ni iya}. (Suuratu Al-baqorah:165).

 Eleyi ni adamo ti Olohun da mo gbogbo awon eda, won nse afomo fun Un pelu ope, won gbafa fun Un pelu adamo won, gege bi Olohun Oba mimo se royin iyen ninu oro Re pe:

 " تُسَبِّحُ لَهُ السَّمَاوَاتُ السَّبْعُ وَالأَرْضُ وَمَن فِيهِنَّ وَإِن مِّن شَيْءٍ إِلاَّ يُسَبِّحُ بِحَمْدَهِ وَلَـكِن لاَّ تَفْقَهُونَ تَسْبِيحَهُمْ إِنَّهُ كَانَ حَلِيماً غَفُوراً " (الإسراء: 44)

{Sanmo mejeeje ati ile ati ohun ti n be ninu won nse afomo fun un, kosi nkankan ayafi ki o maa se afomo pelu idupe fun un, sugbon e ko le ni agboye afomo won, dajudaju O je Ololopo-suuru, Alaforijin}. (Suuratu Al-Israai:44).

Won o maa teriba, ti won o si maa yepere ara wo fun Un, won fe be ni tabi ni tulaasi. Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَلِلّهِ يَسْجُدُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ طَوْعاً وَكَرْهاً وَظِلالُهُم بِالْغُدُوِّ وَالآصَالِ " (الرعد: 15)

{Olohun ni gbogbo ohun ti n be ni sanmo ati ile ati iboji won nfi ori bale fun, ni fife bee tabi ni tulaasi, ni owuro ati ni asala}. (Suuratu Ar-ra'ad:15).

 O ma se o! awon eda miran bi eranko, eye, won gbafa fun adamo won, won si tako mimu ebo sise, ati ijosin fun nkan miran yato si Olohun.

Sulaimon omo daud (ki ola Olohun maa ba awon mejeeji) je eniti Olohun fun un ni ola ti ko fun eni kankan ninu gbogbo aye, Olohun je ategun ati alujonnu nipa fun un, Olohun ti ola Re ga sope:

 " ولِسُلَيْمَانَ الرِّيحَ غُدُوُّهَا شَهْرٌ وَرَوَاحُهَا شَهْرٌ وَأَسَلْنَا لَهُ عَيْنَ الْقِطْرِ وَمِنَ الْجِنِّ مَن يَعْمَلُ بَيْنَ يَدَيْهِ بِإِذْنِ رَبِّهِ وَمَن يَزِغْ مِنْهُمْ عَنْ أَمْرِنَا نُذِقْهُ مِنْ عَذَابِ السَّعِيرِ {12} يَعْمَلُونَ لَهُ مَا يَشَاءُ مِن مَّحَارِيبَ وَتَمَاثِيلَ وَجِفَانٍ كَالْجَوَابِ وَقُدُورٍ رَّاسِيَاتٍ اعْمَلُوا آلَ دَاوُودَ شُكْراً وَقَلِيلٌ مِّنْ عِبَادِيَ الشَّكُورُ {13}" ( سبأ:12-13)

{A je ategun nipa fun sulaimon, irin owuro re se dede irin osu kan, irin asale re se dede irin osu kan, A se yiyo irin doje ni irorun fun, nbe ninu awon alujonnu awon ti won nsise fun un pelu iyonda Olohun, eni ti o ba koti-ikun si ase Wa ninu won, A o fi iya ina (saiir) je. * Won nse ohun ti o ba fe fun un, bi ile ijosin, ere, kanga ti o da gege bi abata, ati awon koko ti o kenu, eyin ara Daud e se ise idupe, oludupe kere ninu awon erusin Mi}. (Suuratu As-sabai:12-13).

 Bakanna Olohun fun ni agboye ede awon eranko, ati agboye oro awon eye, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَوَرِثَ سُلَيْمَانُ دَاوُودَ وَقَالَ يَا أَيُّهَا النَّاسُ عُلِّمْنَا مَنطِقَ الطَّيْرِ وَأُوتِينَا مِن كُلِّ شَيْءٍ إِنَّ هَذَا لَهُوَ الْفَضْلُ الْمُبِينُ" (النمل: 16)

{Sulaimon jogun Daud, o sope: mope eyin eniyan! Won fi isoro eye mo wa, won si fun wa ninu gbogbo nkan, dajudaju eleyi je ola ti o han}. (Suuratu An-naml:16).

O(Sulaiman) je eniti ma nse afeku awon omo ogun re, awon ti won maa nlo mu oriyin wa fun un lati ibuyo orun ni ori ile ati ibuwo re, Olohun ti ola Re ga sope:

 "وَحُشِرَ لِسُلَيْمَانَ جُنُودُهُ مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنسِ وَالطَّيْرِ فَهُمْ يُوزَعُونَ " (النمل:17)

{Won ko awon omo-ogun jo fun Sulaimon, ninu awon alujonnu ati eniyan ati eye, won si nda girigiri}. (Suuratu An-naml:17).

O be won wo ni ojo kan, ko wa ri eye (hudhuda), o wa se emo fun aisi nle re, o si se ileri iya fun un, nitori iyapa re laisi awijare fun un. Kope ni eye naa ba de pelu iroyin nla ti o tako o, ti ko si yonu sii, ni igba ti o ri arabinrin oba iran sabai ati awon ijo re ti won nsin nkan miran yato si Olohun, ti inu Sulaimon ko si yo si eleyi, ko si te lorun. Olohun ti ola Re ga sope:

" وتَفَقَّدَ الطَّيْرَ فَقَالَ مَا لِيَ لَا أَرَى الْهُدْهُدَ أَمْ كَانَ مِنَ الْغَائِبِينَ {20} لَأُعَذِّبَنَّهُ عَذَاباً شَدِيداً أَوْ لَأَذْبَحَنَّهُ أَوْ لَيَأْتِيَنِّي بِسُلْطَانٍ مُّبِينٍ {21} فَمَكَثَ غَيْرَ بَعِيدٍ فَقَالَ أَحَطتُ بِمَا لَمْ تُحِطْ بِهِ وَجِئْتُكَ مِن سَبَإٍ بِنَبَإٍ يَقِينٍ {22} إِنِّي وَجَدتُّ امْرَأَةً تَمْلِكُهُمْ وَأُوتِيَتْ مِن كُلِّ شَيْءٍ وَلَهَا عَرْشٌ عَظِيمٌ {23} وَجَدتُّهَا وَقَوْمَهَا يَسْجُدُونَ لِلشَّمْسِ مِن دُونِ اللَّهِ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ فَهُمْ لَا يَهْتَدُونَ {24} أَلَّا يَسْجُدُوا لِلَّهِ الَّذِي يُخْرِجُ الْخَبْءَ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَيَعْلَمُ مَا تُخْفُونَ وَمَا تُعْلِنُونَ {25} اللَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ {26}" ( النمل:20-26)

{O se abewo awon eye, o wa sope: ki lo de ti mi o ri eye hudhuda, abi ko sin'le ni? * Maa fi iya je e, tabi ki n du, tabi ki o mu arojare ti o fi oju han wa. * O se die ni (o ba de) o wa sope: mo mo ohun ti ire ko mo, mo si mu iroyin amodaju wa fun o lati odo iran sabai. * Dajudaju mo ri arabinrin kan ti o je oba fun won, won fun ninu gbogbo nkan, o si ni aga anla. * Mo ri oun ati awon ijo re ti won n fi ori bale fun orun yato si Olohun, esu si se ise won loso fun won, o seri won kuro ni ojuona, won o si mo ona. * Nje ko ye ki won maa fi ori bale fun Olohun, eni ti o mu irugbin jade ninu ile pelu ojo lati sanmo, O si mo ohun ti e npamo, ati ohun ti e nfi han. * Olohun kosi olohun miran leyin Re, Oba ti o ni aga alarashi nla}. (Suuratu An-naml:20-26).

 

 

Iranse ti o kari gbogbo agbaye ni mimu Olohun ni okan soso:

Ise ijosin fun Olohun ati ise afomo ise fun Un nikan je ipepe gbogbo awon ojiseati awon anobi ti Olohun gbe dide, bere lati ori Anobi Adam ti won si pari pelu igbeyin awon anobi ati awon ojise ti se anobi Muhammad, (ki Olohun se ike ati ola fun gbogbo won). Olohun ti ola Re ga sope:

" وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلَّا نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدُونِ " (الأنبياء:25)

{A o ran ojise kan siwaji re ayafi ki A ranse si pe dajudaju ko si Olohun miran ayafi Emi, e ya maa se ijosin fun Mi}. (Suuratu Al-Anbiyaai:25).

Sayyid Qutub (ki Olohun se ike fun un) sope: "ije okan soso Olohun nipa ijosin, ati nipa awon ise Re, oun ni ije okan soso ti o ye ki won ran gbogbo awon ojise nitori re, oun ni o si ye ki won naa gbogbo awon igbiyanju yi si ona re, oun ni o si ye ki won fi ara da iya ati eta-ero nitori re latayedaye, ki se nitori pe Olohun ni bukata sii, Olohun Oba mimo roro tayo gbogbo agbaye, sugbon nitoripe ki isemi awon eniyan ko le gun rege, ko si le de ibi giga, ko si le ba awon eniyan mu ayafi pelu mimu Olohun ni okan soso, eyi ti oripa re ko ni aala ninu isemi awon eniyan, bakanna ni gbogbo ona".

Ni iberepepe a o wo oripa mimu Olohun ni okansoso pelu oju sunkunu ti a fi wo yi, nibi adamo eniyan fun ara re, ni agbegbe bibe re, bukata re, titopo re … ati oripa re ninu irori re, ati oripa irori yi ninu adamo re, iwoye yi ko opolopo nkan sinu ti n so nipa adamo awon eniyan ni gbogbo ona, ati gbogbo ohun ti o fe, ti o ni bukata si, yio maa da pada si agbegbe kan ti yio ma beere gbogbo ohun ti o fe nibe, agbegbe kan ti yio maa gbero re ti yio si maa beru re, ti yio maa beru ibinu re, ti yio si maa gbero iyoni re, agbegbe kan ti ikapa gbogbo nkan be lowo re, nitori pe oun ni o da gbogbo nkan, oun si ni nse eto re, (eleyi ntumo si Olohun Oba ti ola Re ga).

Be naa ni won o da adamo omo-eniyan pada si ipile kan, ti yio maa gba iwoye re, agboye re ati iwa re lati ibe, ti yio si maa ri esi lodo re fun ibere ti n lo ti nbo ninu okan re, yio si maa je esi fun gbogbo ibere awon nkan ti n be laye, ati ohun ti n semi, ati eniyan.

Bayi ni adamo yii o se kojo, ninu iwoye, iwa, irori ati ise sise nipa adi sokan ati ilana, nipa aye fifa ofin yo, ati nipa isemi ati iku, nipa lilo-bibo, nipa alaafia ati ije-imu, nipa isemi aye ati ati ojo ikeyin, (adamo yi) ko ni si ona, ko si ni ya si ona otooto, ko si ni gba orisirisi laisi afenuko lori won".

Bi Olohun se sa awon ojise lesa to pelu iranse, ati aponle lodo Olohun, ati ife Re si won, ti gbogbo eleyi won o gbodo sin won, won o si gbodo gbe iran kan ninu awon iran ijosin fun won, Olohun ti ola Re ga sope:

" مَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُؤْتِيَهُ اللّهُ الْكِتَابَ وَالْحُكْمَ وَالنُّبُوَّةَ ثُمَّ يَقُولَ لِلنَّاسِ كُونُواْ عِبَاداً لِّي مِن دُونِ اللّهِ وَلَـكِن كُونُواْ رَبَّانِيِّينَ بِمَا كُنتُمْ تُعَلِّمُونَ الْكِتَابَ وَبِمَا كُنتُمْ تَدْرُسُونَ وَلاَ يَأْمُرَكُمْ أَن تَتَّخِذُواْ الْمَلاَئِكَةَ وَالنِّبِيِّيْنَ أَرْبَاباً أَيَأْمُرُكُم بِالْكُفْرِ بَعْدَ إِذْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ }" (آل عمران:79-80)

{Ko too fun eniyan kan ki Olohun fun un ni tira ati idajo ati ije anobi, leyin nan ki o wa so fun awon eniyan pe: e je erusin fun mi yato si Olohun, sugbon (yio sope): e je eni Olohun, pelu kiko (awon eniyan) ni tira ati fifi mo won. Ko ni payin lase ki e mu awon malaika ati awon anobi ni olohun, nje yio payin lase ikofun Olohun leyin igba ti e ti je musulumi?} (Suuratu Aal Imraan:79-80).

Nuhu ojise akoko ti won ranse leyin anobi Adam (ola ki o maa awon mejeeji), o lo egberun odun ayafi aadota laarin awon ijo re, o lo gbogbo awon orisirisi ona ipepe bi iseni-lojukokoro, iderubani, ipepe ni koko, ipepe ni gbangba, ki o le da awon ijo re pada si ibi mimu Olohun ni okan soso, ati ijosin fun Olohun nikan, leyin igba ti ebo ti fonka laarin won. Olohun ti ola Re ga sope:

" لَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحاً إِلَى قَوْمِهِ فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُواْ اللَّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَـهٍ غَيْرُهُ إِنِّيَ أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ" (الأعراف:59)

{Dajudaju, A ran Nuha si awon ijo re, o so fun won pe: eyin ijo mi! esin Olohun, ko si olohun miran fun yin yato Si, emi nberu iya ojo nla lori yin}. (Suuratu Al-A'roof:59).

 Leyin naa, gbogbo igba ti awon eniyan ba ti nseri kuro nibi ijosin fun Olohun ni Olohun ngbe ojise ati anobi dide si won ki won le tun esin won se, ki won si da won pada si ibi mimu Olohun ni okan soso, ki won si yo won kuro ni oju ona ina. Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولاً أَنِ اعْبُدُواْ اللّهَ وَاجْتَنِبُواْ الطَّاغُوتَ فَمِنْهُم مَّنْ هَدَى اللّهُ وَمِنْهُم مَّنْ حَقَّتْ عَلَيْهِ الضَّلالَةُ فَسِيرُواْ فِي الأَرْضِ فَانظُرُواْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ }" (النحل:36)

{Dajudaju, A gbe ojise dide si gbogbo ijo kookan, (ki won sofun awon eniyan pe): e sin Olohun, ki e si jinnan si gbogbo nkan ti won njosin fun yato si Olohun, nbe ninu won eni ti Olohun fi onan mo, o si n be ninu won eni ti anuti di tulasi lori re, idi eleyi e rin ni ori ile, ki e wo bi igbeyin awon opuro se ri}. (Suuratu An-nahl:36).

Ibrahim baba awon anobi (ola Olohun ki o maa ba) ni igba ti o ri pe awon ijo re nbe lori ebo sise, o ba won se ifanfa lori awon nkan ti won njosin fun yato si Olohun, o fi apejuwe lele lati inu laakai, ti yio je ki o han si won pe ori ibaje ni won wa. Olohun ti ola Re ga sope:

" وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ لأَبِيهِ آزَرَ أَتَتَّخِذُ أَصْنَاماً آلِهَةً إِنِّي أَرَاكَ وَقَوْمَكَ فِي ضَلاَلٍ مُّبِينٍ {74} وَكَذَلِكَ نُرِي إِبْرَاهِيمَ مَلَكُوتَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَلِيَكُونَ مِنَ الْمُوقِنِينَ {75} فَلَمَّا جَنَّ عَلَيْهِ اللَّيْلُ رَأَى كَوْكَباً قَالَ هَـذَا رَبِّي فَلَمَّا أَفَلَ قَالَ لا أُحِبُّ الآفِلِينَ {76} فَلَمَّا رَأَى الْقَمَرَ بَازِغاً قَالَ هَـذَا رَبِّي فَلَمَّا أَفَلَ قَالَ لَئِن لَّمْ يَهْدِنِي رَبِّي لأكُونَنَّ مِنَ الْقَوْمِ الضَّالِّينَ {77} فَلَمَّا رَأَى الشَّمْسَ بَازِغَةً قَالَ هَـذَا رَبِّي هَـذَا أَكْبَرُ فَلَمَّا أَفَلَتْ قَالَ يَا قَوْمِ إِنِّي بَرِيءٌ مِّمَّا تُشْرِكُونَ {78} إِنِّي وَجَّهْتُ وَجْهِيَ لِلَّذِي فَطَرَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ حَنِيفاً وَمَا أَنَاْ مِنَ الْمُشْرِكِينَ {79}" (الأنعام:74-79)

{Nigbati Ibrahim so fun baba re Aasara: nje wa mu awon orisa ni Olohun, dajudaju, mo ri iwo ati awon ijo re ninu anu ti o han kedere. * Bayi ni A fi awon ijoba sanmo ati ile han Ibrahim ki o le maa be ninu awon alamodaju. * Nigbati ile su ori irawo kan, o sope: nje eleyi ni Oluwa mi? nigbati ti o(irawo naa) wokun, o sope: mi o ni fe si awon awookun. * Nigbati o ri osupa ti o yo, o sope: nje eleyi ni Oluwa mi? nigbati o wokun, o sope: ti Olohun ko ba fi ona mo mi inu awon ijo ti o si sonu ni maa wa. * Nigbati o orun ti o yo, o sope: nje eleyi ni Oluwa mi? eyi ni o tobji ju, nigbati o wookun o sope: e yin ijo mi! Dajudaju, emi mowo-mose nibi ohun ti e sin leyin Olohun. * Dajudaju emi doju mi ko Eni ti o da sanmo ati ile, mo je oluse esin ni mimo fun Olohun, mi o si ninu awon elebo}. (Suuratu Al-An'aam:74-79).

Yaqub baba awon omo (isireli) (ki Olohun se ola fun un) o mojuto siseku adisokan mimu Olohun ni okan soso, ati didabo boo ti yio fi maa lo gbere leyin re. Ninu asokale re fun awon omo re nigba ipokaka iku re, ti emi fe jade lara re, bi asiko yi se soro to, ti ironu lati inu okan wa si le koko, ero re ti otobi ju ni bawo ni adisokan ije okan soso Olohun yio se seku ati ije eru fun Olohun nikan. Olohun ti ola Re ga so nipa re pe:

" أَمْ كُنتُمْ شُهَدَاء إِذْ حَضَرَ يَعْقُوبَ الْمَوْتُ إِذْ قَالَ لِبَنِيهِ مَا تَعْبُدُونَ مِن بَعْدِي قَالُواْ نَعْبُدُ إِلَـهَكَ وَإِلَـهَ آبَائِكَ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ إِلَـهاً وَاحِداً وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ " (البقرة:133)

{Nje e je olujeri nigba ti asiko iku Yaqub to, nigba ti n so fun awon omo re pe: kini e o maa sin leyin mi? won sope: a o maa sin Olohun re, Olohun awon baba re (Ibrahim, Ismaheel, Ishaq) Olohun kan soso, awa gbafa fun un}. (Suuratu Al-baqorah:133).

Anobi Yusuf (ola Olohun ki o maa ba) leyin igba ti won fi sinu ewon, aayun inu ewon ati ilekoko jijina si awon awon ara ati eta-ero abosi ko ni ki o gbagbe ipepe si imu Olohun ni okan ati imo josin fun Un larin awon ti o wa pelu re ninu awon elewon. Olohun ti ola Re ga sope:

 " يَا صَاحِبَيِ السِّجْنِ أَأَرْبَابٌ مُّتَفَرِّقُونَ خَيْرٌ أَمِ اللّهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ {39} مَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِهِ إِلاَّ أَسْمَاء سَمَّيْتُمُوهَا أَنتُمْ وَآبَآؤُكُم مَّا أَنزَلَ اللّهُ بِهَا مِن سُلْطَانٍ إِنِ الْحُكْمُ إِلاَّ لِلّهِ أَمَرَ أَلاَّ تَعْبُدُواْ إِلاَّ إِيَّاهُ ذَلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَـكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لاَ يَعْلَمُونَ {40}" (يوسف:39-40)

{Mope eyin mejeeji ti e je alabagbe mi ninu ewon! Nje awon oluwa otooto ni won lore ju ni abi Olohun okan soso, Olubori? * E ko josin fun nkan miran yato sii ayafi awon oruko kan ti e so won eyin ati awon baba yin, Olohun ko so iyonda re kale fun yin, idajo ko je ti enikan ayafi ti Olohun, O pase ki e ma sin (nkan miran) ayafi Oun naa, eleyi ni esin ti o duro deede, sugbon opolopo ninu awon eniyan won ko mo bee}. (Suuratu yusuf:39-40).

Anobi Musa (ike ati ola ki o maa ba) ni igba ti awon ijo re bere lowo re ni asiko ti won rekoja lodo awon ijo kan ti won nsin orisa pe ki o gbe olohun kan kale ti awon o maa sin in gege bi (awon ijo naa se sin awon orisa won) o wa se alaye paapa awon olohun ti won nsin wonyi yato si Olohun, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَائِيلَ الْبَحْرَ فَأَتَوْاْ عَلَى قَوْمٍ يَعْكُفُونَ عَلَى أَصْنَامٍ لَّهُمْ قَالُواْ يَا مُوسَى اجْعَل لَّنَا إِلَـهاً كَمَا لَهُمْ آلِهَةٌ قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ تَجْهَلُونَ {138} إِنَّ هَـؤُلاء مُتَبَّرٌ مَّا هُمْ فِيهِ وَبَاطِلٌ مَّا كَانُواْ يَعْمَلُونَ {139} قَالَ أَغَيْرَ اللّهِ أَبْغِيكُمْ إِلَـهاً وَهُوَ فَضَّلَكُمْ عَلَى الْعَالَمِينَ {140}" (الأعراف:138-140)

 {A mu awon omo isisreli koja lori ibudo nan, won wa koja lodo awon ijo kan ti won rababa lodo awon orisa won, won sope: ire musa! Gbe olohun kan sile fun wa gege bi awon nan se ni awon olohun ti won, o sope: dajudaju ijo alaimokan niyin. * Dajudaju awon wonyi ohun ti won wa lori re je nkan ti won o parun, ohun ti won si nse je ohun ibaje. * O sope: nje maa mu elomiran ti o yato si Olohun ni oloun fun yin? Oun si ni O gbe ola fun yin lori gbogbo agbaye}. (Suuratu Al-A'roof:138-140).

Leyin re ni Isa omo Maryam (ola Olohun ki o maa ba) won gbe dide si awon omo isireli nigba ti won sonu ti won si tako ofin anobi musa (ola Olohun ki o maa ba), ti won fi anobi Olohun (Uzairu) kegbe pelu Olohun, ki o le da won pada si ona ti o too, Olohun ti ola Re ga sope:

"لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُواْ إِنَّ اللّهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ وَقَالَ الْمَسِيحُ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اعْبُدُواْ اللّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ إِنَّهُ مَن يُشْرِكْ بِاللّهِ فَقَدْ حَرَّمَ اللّهُ عَلَيهِ الْجَنَّةَ وَمَأْوَاهُ النَّارُ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ " (المائدة:72)

{Dajudaju, awon ti won sope: dajudaju olohun ni Mosihu (isa) omo Moriyam ti ya alaigbagbo, Mosihu si sope: e yin omo isireli! E sin Olohun Oluwa mi ati Oluwa yin, dajudaju eni ti o ba sebo pelu Olohun, Olohun ti se ogba idera ni eewo fun, ibugbe re si ni inan, ko si oluranlowo fun awon alabosi}. (Suuratu Al-Maidah:72).

Igbeyin awon anobi ati awon ojise (anobi Muhammad) (ki Olohun se ike ati ola fun un) won gbe dide si awon ijo kan ti won ti gbe ona mimo ju sile, ti won wa njosin fun awon igi ati okuta, o lo odun mokanla laarin won pelu pe o n se abewo aye ikojo won, ti nsi pe won pe: " e sope: kosi olujosin fun miran lododo ayafi Olohun e o jere" (Ibn Hibban).

 Eleyi ni iranse ti Olohun fi ranse si gbogbo awon ojise, ki won se ijosin ni paapa fun Olohun, eleyi si ni oro ti won fi nbere fun awon ijo won.

" يَا قَوْمِ اعْبُدُواْ اللّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَـهٍ غَيْرُهُ " (هود:50)

 {Mope eyin ijo mi! e sin Olohun, ko si olohun miran fun yin yato Sii}. (Suuratu Hud:50).

Sayyid Qutub (ki Olohun se ike fun un) sope: "Ti o ba jepe paapa ijosin je isise to awon ami ijosin lasan ni, ki ba ti ni bukata si pipo awon ojise yi, ki ba ti ni bukata si awon igbiyanju ti muni ru ti awon ojise se (ike ati ola Olohun ki o maa ba won), ki ba ti ni bukata si awon ijeniya ati awon eta-ero ti awon olupepe nri ati awon olugbagbo ododo ni gbogbo igba! Dajudaju, ohun ti gbogbo wahala ati isoro yi da le lori ni mimu awon eniyan jade kuro nibi ijosin fun awon eda losi ibi ijosin fun Olohun nikan soso nibi gbogbo nkan, ati nibi gbogbo ilana isemi won ni aye ati ni ojo ikeyin".

 

 

Ibere ihan ebo sise:

Ni ibere pepe awon eniyan nbe lori esin adamo ati sise Olohun ni okan, lati ori anobi Adam (ola Olohun ki o maa ba), ko si ebo ni ori ile, ayafi ni asiko awon ijo anobi Nuhu (ola Olohun ki o maa ba) ti o je abajade aseju won nipa gbigbe awon enirere tobi ati awon aayo Olohun. Awon ijo re yii gbe orisa kale ki won le maa ranti awon enirere ninu won, leyin igba die awon iko miran de leyin won, ti esu si ko royiroyi si won lokan pe awon baba won ko gbe awon orisa yi kale lasan ayafi nitori alubarika ati ipo won, bayi ni won bere si ni josin fun won leyin won, Olohun ti ola re ga sope:

 " وَقَالُوا لَا تَذَرُنَّ آلِهَتَكُمْ وَلَا تَذَرُنَّ وَدّاً وَلَا سُوَاعاً وَلَا يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسْراً " ( نوح: 23)

{Won sope: e ma fi awon olohun yin sile, e ma fi sile awon orisa (wadda), (suwaha), (yagutha), (yahuqo) ati (nasran)}. (Suuratu An-nuh:23).

Ibn Abbas ti o je onimimo ninu ijo yi, ti o je eni ti o mo nipa itumo Al-Qur'an sope: "awon orisa yi je oruko fun awon enirere ninu awon ijo nuh, leyin igba ti won papoda esu ranse si awon ti won wa leyin won pe: e gbe ere si aye ijoko won ki e so won ni oruko won, ki e le maa ranti won, won se bee, sugbon won o josin fun won titi ti awon wonyi fi papoda, won ti gbagbe idi ti won fi gbe won sibe, bayi ni won bere si ni josin fun won leyin Olohun". (Al-Bukhaari).

Bibe ebo ati orisirisi awon ohun ti awon eniyan njosin fun ni ori ile ntoka si wiwa bukata awon eniyan si Olohun kan ti won o maa josin fun un, atipe ibere pepe won je lori mimu Olohun ni okan soso, sugbon nigba ti asiko pe larin won ati awon anobi ati awon ojise won esu se awon ise kan ni oso fun won ki o le je ona lati mu olohun miran ti won o maa josin fun un pelu Olohun ododo.

Ijosin fun nkan miran yato si Olohun ni ona orisirisi. Ninu re ni:

1 - Ijosin fun awon aayo ati awon enirere gege bi ise awon ijo anobi Nuh (ki ola Olohun maa ba). Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَقَالُوا لَا تَذَرُنَّ آلِهَتَكُمْ وَلَا تَذَرُنَّ وَدّاً وَلَا سُوَاعاً وَلَا يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسْراً " (نوح:23)

{Won sope: e ma fi awon olohun yin sile, e ma fi sile awon orisa (wadda), (suwaha), (yagutha), (yahuqo) ati (nasran)}. (Suuratu An-nuh:23).

2 - Ijosin fun awon okuta, igi, ere ati awon orisa, gegebi ise awon ijo Ibrahim (ola Olohun ki o maa ba) nipa gbigbe awon okuta ati awon pako ti won o si sodi olohun ti won o maa josin fun leyin Olohun ododo. Olohun ti ola Re ga so lori ahan anobi Ibrahim (ola Olohun ki o maa ba) leni ti n tako ise awon ijo re:

" قَالَ أَتَعْبُدُونَ مَا تَنْحِتُونَ وَاللَّهُ خَلَقَكُمْ وَمَا تَعْمَلُون" (الصافات:95-96)

{O sope: nje e o maa josin fun ohun ti e gbe. Olohun ni O se eda yin ati ohun ti e nse}. (Suuratu As-sofaat:95-96).

 3 - Ijosin fun awon irawo, orun ati osupa, gege bi ise awon ijo obinrin ti o je oba iran sabai ni asiko anobi Sulaimon (ola Olohun ki o maa ba), ti eye hudhud fun un ni iro nipa won gege bo se gbawaju lo. Olohun ti ola Re ga sope:

" وَجَدتُّهَا وَقَوْمَهَا يَسْجُدُونَ لِلشَّمْسِ مِن دُونِ اللَّهِ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ فَهُمْ لَا يَهْتَدُونَ" (النمل:24)

{Mo ri oun ati awon ijo re ti won n fi ori bale fun orun yato si Olohun, esu si se ise won loso fun won, o seri won kuro ni ojuonan, won o si mo ona}. (Suuratu An-naml:24).

4 - Ijosin fun awon eniyan gege bi awon ijo Firhaona se se. Olohun ti ola Re ga sope:

 " {وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ مَا عَلِمْتُ لَكُم مِّنْ إِلَهٍ غَيْرِي فَأَوْقِدْ لِي يَا هَامَانُ عَلَى الطِّينِ فَاجْعَل لِّي صَرْحاً لَّعَلِّي أَطَّلِعُ إِلَى إِلَهِ مُوسَى وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ مِنَ الْكَاذِبِينَ" (القصص:38)

{Firiaona sope: e yin olola mi o mo olohun miran fun yin yato simi, ire hamonu yo buloku lati ara amo ki mo petesi kan fun mi, boya maa foju ganni Olohun Musa, dajudaju mo ro wipe nbe ninu awon opuro}. (Suuratu Al-Qasos:38).

5- Ijosin fun awon eranko gege bi awon ijo Musa se se. Olohun ti ola Re ga sope:

" فَأَخْرَجَ لَهُمْ عِجْلاً جَسَداً لَهُ خُوَارٌ فَقَالُوا هَذَا إِلَهُكُمْ وَإِلَهُ مُوسَى فَنَسِيَ {88} أَفَلَا يَرَوْنَ أَلَّا يَرْجِعُ إِلَيْهِمْ قَوْلاً وَلَا يَمْلِكُ لَهُمْ ضَرّاً وَلَا نَفْعاً {89} وَلَقَدْ قَالَ لَهُمْ هَارُونُ مِن قَبْلُ يَا قَوْمِ إِنَّمَا فُتِنتُم بِهِ وَإِنَّ رَبَّكُمُ الرَّحْمَنُ فَاتَّبِعُونِي وَأَطِيعُوا أَمْرِي {90} قَالُوا لَن نَّبْرَحَ عَلَيْهِ عَاكِفِينَ حَتَّى يَرْجِعَ إِلَيْنَا مُوسَى {91}" (طه:88-91)

{O mu ogedengbe malu kan jade fun won ti o ni ohun, won sope: eleyi ni olohun wa ati olohun Musa sugbon o gbagbe (lati so). * Nje won o ri wipe ko da oro pada fun won, ko si le fi inira kan won tabi se won ni anfaani? * Dajudaju, Harunan ti so fun tele pe: eyin ijo mi dajudaju won fi se adanwo fun yin ni, dajudaju Oluwa yin ni Oba Ajoke-aye e ya tele mi, ki e si tele ase mi. * Won sope: a ko ni jawo leni ti yio maa josin fun un titi ti Musa yio fi pada de}. (Suuratu Toha:88-91).

6 - Ijosin fun awon anobi ati awon ojise, gege bi awon eni anu ninu awon yahudi ati awon ijo kirisiti se se. Olohun ti ola Re sope:

" وَقَالَتِ الْيَهُودُ عُزَيْرٌ ابْنُ اللّهِ وَقَالَتْ النَّصَارَى الْمَسِيحُ ابْنُ اللّهِ ذَلِكَ قَوْلُهُم بِأَفْوَاهِهِمْ يُضَاهِؤُونَ قَوْلَ الَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَبْلُ قَاتَلَهُمُ اللّهُ أَنَّى يُؤْفَكُونَ" (التوبة:30)

(Awon yehudi so pe: Usairu ni omo Olohun, awon nosora (ijo kirisi) sope: Mosiu (isa) ni omo Olohun, oro ori ahan won lasan ni iye, won nkose oro awon ti won se aigbagbo siwaju (won), Olohun sebi le won, to ri kini won fi n se adapa iro}. (Suuratu At-taoba:30).

7 - Ijosin fun awon igi gege bi awon ijo Shuaib (ola Olohun ki o maa ba) se se. Olohun ti ola Re ga sope:

" كَذَّبَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ الْمُرْسَلِينَ {176} إِذْ قَالَ لَهُمْ شُعَيْبٌ أَلَا تَتَّقُونَ {177} إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ {178} فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ {179}" (الشعراء:176-179)

{Awon ara ogba oko pe awon ojise niro. * Ni igba ti Shuaib so fun won pe: se koye ki e beru Olohun. * Dajudaju emi je ojise olufokantan si yin. * E beru Olohun ki e si tele mi}. (Suuratu Ash-shuarai:176-179).

8 - Ijosin fun awon okuta, igi, ere ati orisa, gege bi awon elebo ninu awon larubawa se se. Olohun ti ola Re ga sope:

 " أَفَرَأَيْتُمُ اللَّاتَ وَالْعُزَّى {19} وَمَنَاةَ الثَّالِثَةَ الْأُخْرَى {20} أَلَكُمُ الذَّكَرُ وَلَهُ الْأُنثَى {21} تِلْكَ إِذاً قِسْمَةٌ ضِيزَى {22} إِنْ هِيَ إِلَّا أَسْمَاء سَمَّيْتُمُوهَا أَنتُمْ وَآبَاؤُكُم مَّا أَنزَلَ اللَّهُ بِهَا مِن سُلْطَانٍ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَمَا تَهْوَى الْأَنفُسُ وَلَقَدْ جَاءهُم مِّن رَّبِّهِمُ الْهُدَى {23}" (النجم:19-23)

{Nje e o ri orisa (laata) ati (uzza). * Ati (monata) ti o se ikeeta? * Nje ti yin ni ako, ti ti e si je abo? * Iye je ipin abosi. * Dajudaju won o je nkankan ayafi awon oruko kan ti e so, eyin ati awon baba yin, Olohun ko so eri kankan kale fun, won o tele nkankan ayafi aba-dida ati ohun ti awon emi nfe, dajudaju, onamo ti de wa bawon lati dodo Oluwa won}. (Suuratu An-najm:19-23).

To ba ri bee, itase-agere awon ijo ti o ti siwaju kuro nibi mimu Olohun ni okan soso, ati kiko sinu ebo sise o sele lati ara gbigbe titobi fun awon enirere ninu won, ati gbigbe ere ati yiya aworan won lati le maa fi ranti ola ti n be fun won ati awon iwa eyin won. Eleyi ni ohun ti ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) se alaye re fun iya habeebah ati iya salamoh nigba ti won so nipa ile ijosin kan ti won ri ni ilu Habasha, ti won npe ni (mariyyah), awon aworan si wa ni inu re, ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) sope: [Awon won yen ni eniti o se pe ti enirere ninu won ba papoda, won o mo mosalasi si ori sare re, won o si ya awon aworan yen si be, awon wonyi ni eni buruku lodo Olohun ni ojo igbende]. (Muslim).

 

 

Awon okunfa ti o je ki ijosin fun nkan miran yato si Olohun han:

Olohun salaye pe awon ona mimo ati agboye ni igboro, irina ati lakai, ati ibe ni awon eniyan o ti maa mo ohun ti n lo laarin won ninu aye. Olohun ti o tobi sope:

" وَاللّهُ أَخْرَجَكُم مِّن بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ لاَ تَعْلَمُونَ شَيْئاً وَجَعَلَ لَكُمُ الْسَّمْعَ وَالأَبْصَارَ وَالأَفْئِدَةَ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ " (النحل:78(

{Olohun mu yin jade lati inu iya yin (ni igbana) e o mo nkankan, o se igboro, awon irinan ati awon okan fun yin, ki e le dupe}. (Suuratu An-nahl:78).

Awon ona yi ni eniyan o maa gba riran, gboro, ronu. Oni-laakai ti yio je eniti won fi se konge daada ni eni ti yio je olugbagbo ododo fun Oluseda re lati ara awon nkan wonyi. Olohun ti ola Re ga sope:

"قُلِ انظُرُواْ مَاذَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَمَا تُغْنِي الآيَاتُ وَالنُّذُرُ عَن قَوْمٍ لاَّ يُؤْمِنُونَ " (يونس:101)

{Sope: e wo ohun tin be ni awon sanmo ati ile, awon aamin ati ikilo ko le wulo fun awon ijo ti won ko Gbagbo}. (Suuratu yunus:101).

Sayyid Qutub (ola Olohun ki o maa ba) sope: " Ti o ba je pe eniyan ronu si sise eda re, eya re, awon nkan igbonmo ti won fun, orikerike ara re, awon agbara ati oye ti won fun ko ba mo Olohun, yio si mona losi odo Re pelu awon ohun arisenmo ti ntoka pe Oun ni Adeda kan soso, ko si enikan ti o ni agbara lati da awon eda, kekere ninu won tabi nlanla won, (ti a ba so nipa) igbaro bawo ni o se nsise? Bawo ni o se gboro? Bakanna ni irina bawo ni o se nrina? Bawo ni o se he awon imole ati awon orisirisi nkan, bakanna, ki ni okan? Bawo ni o se n ni igbonmo, bawo ni o se nmo gbogbo nkan, mimo adamo awon nkan igbonmo yi lasan ati agbara won ati bi won se n sise to ni arisenmo ni agbaye awon eniyan, bawo ni won se eda won, ti won gbe won gun ara won lona ti o se remu pelu adamo aye ti awon eniyan se emi ninu re yi? Ti o ba mehe ni igba die ninu akoko ko ni le sise bo se ye, eti ko ni le gboro, oju ko ni le rina, sugban Alagbara ti ndari aye O se eto adamo eniyan ni ohun ti o ba adamo aye ti n semi ninu re mu, ni gbogbo nkan fi n lo bo se ye, o kan je pe eniyan ko dupe idekun yi, Olohun ti ola Re ga sope:

"قَلِيلًا ما تَشْكُرُونَ" (المؤمنون:78)

{Igba die ni e fi ndupe}. (Suuratu Al-mu'minoon:78(.

 Idupe bere lati ibi mimo eni ti o funni ni idera, ati gbigbe e tobi pelu awon iroyin re, leyin na ni sise ijosin fuu un ni Oun nikan, Oun nikan ni awon oripa ise Re ntoka si okan soso Re.

Tori idi yi ni awon aaya Al-Qur'an fi nba eniyan soro lati ara awon ona yi, o si se loju kokoro lati ronu si awon agbara nlanla ti awon ona yi muwa baa lori awon eda ti n be ni agbaye, ki o le mo pe oun ko ni o da ara re, ko si mo be lasan. Olohun ti ola Re ga sope:

" أَمْ خُلِقُوا مِنْ غَيْرِ شَيْءٍ أَمْ هُمُ الْخَالِقُونَ {35} أَمْ خَلَقُوا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بَل لَّا يُوقِنُونَ {36}" (الطور:35-36)

{Nje won se eda won laisi nkankan? Abi awon ni aseda? Abi awon ni won se eda awon sanmo ati ile? Ko ri bee! Won o ni amodaju}. (Suuratu At-tur:35).

Ni igba miran ibanisoro yio je ti awon onilaakai, awon ti won nlo laakai won lati fi wa ododo, ti won o si maa fi agbaye yii se eri lori bibe Olohun ti O se eda re, won o mo pe gbogbo ohun ti nbe ni o ni eni ti o se e, gbogbo ohun ti won da naa ni o ni eni ti o se eda re, gbogbo okunfa naa ni oni eni ti o se okunfa re, Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَاخْتِلاَفِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَالْفُلْكِ الَّتِي تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِمَا يَنفَعُ النَّاسَ وَمَا أَنزَلَ اللّهُ مِنَ السَّمَاءِ مِن مَّاء فَأَحْيَا بِهِ الأرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَآبَّةٍ وَتَصْرِيفِ الرِّيَاحِ وَالسَّحَابِ الْمُسَخِّرِ بَيْنَ السَّمَاء وَالأَرْضِ لآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ " (البقرة:164)

{Dajudaju, (aami nbe fun awon onilaakai) nibi dida awon sanmo ati ile, lilo-bibo oru ati osan, oko oju-omi tin lo ninu ibudo pelu awon nkan ti n se awon eniyan ni anfaani, ojo ti Olohun so kale lati sanmo ti O fi ye ile leyin iku re, O si fon orisirisi awon eranko ka si ori re, ati fife ategun, ati esu-ojo ti won je nipa larin sanmo ati ile}. (Suuratu Al-Baqorah:164).

Ni igba miran awon aaya Al-qur'an won seni ni ojukokoro ti won o si pani ni ase ironu ati iwoye si awon aami Olohun ti a n ri ni aye yii, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ إِذَا أَنتُم بَشَرٌ تَنتَشِرُونَ {20} وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجاً لِّتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ {21} وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِّلْعَالِمِينَ {22} وَمِنْ آيَاتِهِ مَنَامُكُم بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَابْتِغَاؤُكُم مِّن فَضْلِهِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ {23} وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفاً وَطَمَعاً وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَيُحْيِي بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ {24} وَمِنْ آيَاتِهِ أَن تَقُومَ السَّمَاء وَالْأَرْضُ بِأَمْرِهِ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِّنَ الْأَرْضِ إِذَا أَنتُمْ تَخْرُجُونَ {25}" ( الروم:20-25)

{Ninu awon aami Re ni dida ti O da yin lati ara erupe, leyin naa ni e o je eniyan ti e o fonka (si ori ile aye). *Ninu awon aami Re ni dida ti O da awon iyawo lati ara yin, ki e le fi arabale si odo won, O si se ife ati aanu si arin yin, dajudaju, aami nbe nibi iyen fun awon ijo ti nronu. * Ninu awon aami Re ni sise eda awon sanmo ati ile, ati yiyato awon ede ati awo yin, dajudaju, aami nbe nibi iyen fun awon onimimo. * Ninu awon aami Re ni kikun yin loorun ni oru ati osan, ati wiwa ti e nwa ola Re, dajudaju, aami nbe nibi iyen fun awon ijo ti won ngboro. * Ninu aami Re ni monamona ti n fun yin ri ti o nje iberu ati ohun itanmo, O si n so ojo kale lati sanmo, leyin naa Yio fi ye ile leyin iku re, dajudaju, aami nbe nibi iye fun awon ijo ti n se laakai. * Ninu awon aami Re ni diduro sanmo ati ile pelu ase Re, leyin naa nigba ti O ba peyin lati ile leekannaa ni e o maa jade}. (Suuratu Ar-ruum:20-25).

Ni igba miran awon aaya Al-Qur'an o pase lilo irina lati fi wo awon nkan ti a n ri ni ayika wa, Olohun ti ola Re ga sope:

" قُلِ انظُرُواْ مَاذَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَمَا تُغْنِي الآيَاتُ وَالنُّذُرُ عَن قَوْمٍ لاَّ يُؤْمِنُونَ " (يونس:101)

{Sope: e wo ohun tin be ni sanmo ati ile, awon aami ati ikilo ko le wulo fun awon ijo alaigbagbo}. (Suuratu Yunus:101).

Ni igba miran awon aaya o pase imo ronu ti o maa muni mo Olohun, Olohun ti ola Re ga sope:

" خَلَقَ السَّمَاوَاتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا وَأَلْقَى فِي الْأَرْضِ رَوَاسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمْ وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَابَّةٍ وَأَنزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ {10} هَذَا خَلْقُ اللَّهِ فَأَرُونِي مَاذَا خَلَقَ الَّذِينَ مِن دُونِهِ بَلِ الظَّالِمُونَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ {11}" ( لقمان:10-11)

{O da awon sanmo ati ile lai si opo ti e nfi oju ri, osi ju awon oke si ori ile ki o maa ba rii moyin lese, O si fon awon orisirisi eranko ka si ori re, A so ojo kale lati sanmo, A leyin Re se eda, awon alabosi nbe ninu anu ti o han}. (Suuratu luqman:10-11).

Ni igba miran awon aaya o pase igboro ati idake jeje fun ohun ti won nso, leyin naa ni sise ironu ati gbagba eyi ti o ni alaafia ni be ati eyi ti o dara julo, Olohun ti ola Re ga sope:

" هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ لِتَسْكُنُواْ فِيهِ وَالنَّهَارَ مُبْصِراً إِنَّ فِي ذَلِكَ لآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ " (يونس:67)

{Oun ni o se oru fun yin ki e le fi ara bale ninu re, O si se osan ni ohun ti nrinan, dajudaju, awon aami nbe nibi iye fun awon ijo ti n gboro}. (Suuratu Yunus:67).

Ni igba miran awon aaya o pa eniyan lase wiwo awokogbon nibi awon nkan ti nbe ni ayika re, ki o si se anfaani lara re, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَإِنَّ لَكُمْ فِي الأَنْعَامِ لَعِبْرَةً نُّسْقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهِ مِن بَيْنِ فَرْثٍ وَدَمٍ لَّبَناً خَالِصاً سَآئِغاً لِلشَّارِبِينَ {66}" (النحل:66)

{Dajudaju, awokogbon nbe fun yin nibi awon eran-osin, A n fun yin ni wara ti o mo kanga mu, ti mimu re si rorun fun awon ti won nmu, ninu ohun ti n be ni inu re laarin igbe ati eje}. (Suuratu An-Nahl:66).

 O tun so bakanaA pe:

" وَأَرْسَلْنَا الرِّيَاحَ لَوَاقِحَ فَأَنزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَسْقَيْنَاكُمُوهُ وَمَا أَنتُمْ لَهُ بِخَازِنِينَ " (الحجر:22)

{A fi ategun ranse ki o maa ye irugbin, A si so ojo kale lati sanmo, A wa fi fun yin ni omi mu, e o ni agbara lati fi pamo}. (Suuratu Al-Hijr:22).

 O tun so bakanna pe:

" مَرَجَ الْبَحْرَيْنِ يَلْتَقِيَانِ {19} بَيْنَهُمَا بَرْزَخٌ لَّا يَبْغِيَانِ {20} فَبِأَيِّ آلَاء رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ {21}" (الرحمن:19-21)

{O po ibudo mejeeji nan papo, won si paala po. aye kan wa laarin won ti ko le ja papo. awon idekun Oluwa yin wo ni e npe ni iro?}. (Suuratu Ar-rahmon:19-21).

 O tun so bakanna pe:

" وَفِي الأَرْضِ قِطَعٌ مُّتَجَاوِرَاتٌ وَجَنَّاتٌ مِّنْ أَعْنَابٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَى بِمَاء وَاحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَى بَعْضٍ فِي الأُكُلِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ " (الرعد:4)

{O nbe ni ori ile awon ida kan ti won paalapo, ati awon ogba oko kan tie so inanbi be ninu re ati awon irugbin, ati igi-dabidun, eyi ti o ni eso ati eyi ti ko ni eso, won fin omi kan nan sii, eso re si ju arawonlo, dajudaju, awon aami nbe nibi iye fun awon ijo onilaakai}. (Suuratu Ar-ra'd:4).

Sugbon ni ibo ni awon onilaakaye wa? Awon ti won o kogbon, ti won si gba ikilo! Idi niyi ti Olohun fi fi enu ate lu ninu Al-Qur'an awon ti won ki lo awon irinse wonyi fun ironu ati iwoye, gege bi igboro, iriran ati awon okan, O si royin won pelu aigboro, ailesoro ati airiran, awon ti o se pe o ye ki awon irinse ti Olohun se eda re fun won yii se itosona won losi ibi ododo, ti won o fi woye, ti won o si gba ikilo, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَلَقَدْ ذَرَأْنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيراً مِّنَ الْجِنِّ وَالإِنسِ لَهُمْ قُلُوبٌ لاَّ يَفْقَهُونَ بِهَا وَلَهُمْ أَعْيُنٌ لاَّ يُبْصِرُونَ بِهَا وَلَهُمْ آذَانٌ لاَّ يَسْمَعُونَ بِهَا أُوْلَـئِكَ كَالأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ أُوْلَـئِكَ هُمُ الْغَافِلُون" (الأعراف:179(

{Dajudaju, A ti da inan jahanamo fun opolopo awon alujannu ati awon eniyan, won ni awon okan, won o si fi gbo agboye, won ni awon aju, won o fi riran, won ni awon eti, won o fi gboro, awon wonye da gege bi eran-osin koda won sonu (ju won lo), awon wonye ni afonu-for a}. (Suuratu Al-A'roof:179).

 Dajudaju Al –Qur'an ti se alaye awon oga okunfa ti o fa fifonka ijosin fun nkan miran yato si Olohun, ki awon eru Re le jina si i, ki won si le maa sora lati kosi inu re gege bi awon ti won yato si won se kosi inu re. Ninu re ni:

1 - Ikose awon baba won ni ti ikose afoju ati imo tele ijosin won ati awon isesi won, lai se iwadi ni pa re, koda ki o je ibaje, ni (awon nkan) ti laakaye o le gba a wole, adamo ti o ni alaafia o si le fara mo o, Olohun fi enu ate lu awon ti won nkose (isesi kan) lai se igbiyanju lati ronu, tabi lati damu ara won fun wiwa ododo, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْاْ إِلَى مَا أَنزَلَ اللّهُ وَإِلَى الرَّسُولِ قَالُواْ حَسْبُنَا مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءنَا أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لاَ يَعْلَمُونَ شَيْئاً وَلاَ يَهْتَدُونَ" (المائدة:104)

{Ti won ba so fun won pe: e wa sibi ohun ti Olohun so kale ati odo ojise won o sope: ohun ti a ba awon baba wa lori re ti to wa, se won o se bee koda ki awon baba won ma mo nkankan ki won si ma mo ona}. (Suuratu Al-Maaidah:104).

2 - Itele awon ti won npepe si esin ti won je eni enu ni itele ti afoju, iyen pelu gbigba awon oro won wole, ati awon ise won lai se iwadi ati wiwa eri lori re, Olohun ti ola Re ga sope:

" اتَّخَذُواْ أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَاباً مِّن دُونِ اللّهِ وَالْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَمَا أُمِرُواْ إِلاَّ لِيَعْبُدُواْ إِلَـهاً وَاحِداً لاَّ إِلَـهَ إِلاَّ هُوَ سُبْحَانَهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ" (التوبة: 31(

{Won se awon olotu won, awon asiwaju won ati Moseeh omo Maryam ni awon oluwa won yato si Olohun, won o si pa won lase kinnikan ayafi ki won maa sin Olohun kan soso, kosi olohun miran yato Si i, mimo fun un nibi ohun ti won mu ni orogun mo O}. (Suuratu At-taoba:31).

 Itele lori daada je ohun ti a fe ki a se, a ki mo ododo pelu pipo awon eniyan, tabi pelu eni ti o se nkan naa, sugbon won o maa mo o pelu awon eri ati awon oripa, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَإِن تُطِعْ أَكْثَرَ مَن فِي الأَرْضِ يُضِلُّوكَ عَن سَبِيلِ اللّهِ إِن يَتَّبِعُونَ إِلاَّ الظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلاَّ يَخْرُصُونَ" (الأنعام:116)

{Ti o ba tele opolopo awon ti won nbe ni ori ile won o so e nu kuro ni oju ona Olohun, won o tele nkankan ayafi aba dida, won o se nkankan ayafi adapa iro}. (Suuratu Al-An'am:116).

 3 - Itele awon olori, asiwaju ati awon agbalagba ni itele afoju, nitori ati le sunmo won, tabi se ojukokoro si nkan ti nbe ni odo won ninu awon oso isemi aye, ninu awon owo, awon eran-osin, awon nkan oko, tabi lati se agbokante si awon ipo ati idari, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّ اللَّهَ لَعَنَ الْكَافِرِينَ وَأَعَدَّ لَهُمْ سَعِيراً {64} خَالِدِينَ فِيهَا أَبَداً لَّا يَجِدُونَ وَلِيّاً وَلَا نَصِيراً {65} يَوْمَ تُقَلَّبُ وُجُوهُهُمْ فِي النَّارِ يَقُولُونَ يَا لَيْتَنَا أَطَعْنَا اللَّهَ وَأَطَعْنَا الرَّسُولَا {66} وَقَالُوا رَبَّنَا إِنَّا أَطَعْنَا سَادَتَنَا وَكُبَرَاءنَا فَأَضَلُّونَا السَّبِيلَا {67} رَبَّنَا آتِهِمْ ضِعْفَيْنِ مِنَ الْعَذَابِ وَالْعَنْهُمْ لَعْناً كَبِيراً {68}" (الأحزاب: 64-68)

{Dajudaju, Olohun sebi le awon ti won saigbagbo, O si pese ina (Saheer) (elejo fofo) kale fun won. * Won o se gbere ninu re, won o ni ri aayo kan tabi oluranlowo. * Ni ojo ti won o maa yi awon oju won pada ninu ina, won o sope: o se fun wa! Ki bajepe a ti tele Olohun ati ojise na. Won sope: Oluwa wa! Dajudaju, awa tele awon asiwaju wa, ati awon agbalagba wa, ni idi eyi, won si wa lona, Oluwa wa! Fi ilopo iya lona meji je won, ki O si sebi ti o po le won lori}. (Suuratu Al-Ahzab:64-68).

4 - Itele ife-inu lori ohun ti esu se ni oso fun won, ti o si ju si inu okan won, ninu gbigba awon irori won wole, ati nkan ti emi won nfa si, ti yio jeki won ri itelorun lori ohun ti won nfe, won o wa ma lo awon eri lorun sibi ohun ti won nfe, lai seri si ibi imo tabi laakaye, Olohun ti ola Re ga sope:

 " فَإِن لَّمْ يَسْتَجِيبُوا لَكَ فَاعْلَمْ أَنَّمَا يَتَّبِعُونَ أَهْوَاءهُمْ وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنِ اتَّبَعَ هَوَاهُ بِغَيْرِ هُدًى مِّنَ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ " (القصص:50)

{Ti won o ba je ipe re mo wipe won ntele ife inu won ni, atipe tani eni ti o sonu ju eni ti n tele ife-inu re lo, laisi onanmo lati odo Olohun? Dajudaju Olohun ko ni fi onan mo awon ijo alabosi}. (al qosos:50)

 5 - Igberaga ati itanje: Won o mo awon aami Olohun tin be ninu agbaye yi ati ohun ti o ko sinu, sugbon igberaga won ati itanje won yio kodi won nibi igbagbo won nipa eni ti o se eda awon aami naa, gege bi Firaona se se pelu anobi Musa ni igba ti o pe losi ibi ijosin fun Olohun, Olohun ti ola Re ga sope:

 " قَالَ فِرْعَوْنُ وَمَا رَبُّ الْعَالَمِينَ {23} قَالَ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا إن كُنتُم مُّوقِنِينَ {24} قَالَ لِمَنْ حَوْلَهُ أَلَا تَسْتَمِعُونَ {25} قَالَ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ {26} قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ الَّذِي أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ {27} قَالَ رَبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَا إِن كُنتُمْ تَعْقِلُونَ {28} قَالَ لَئِنِ اتَّخَذْتَ إِلَهاً غَيْرِي لَأَجْعَلَنَّكَ مِنَ الْمَسْجُونِينَ {29}" ( الشعراء:23-29)

{Fir'aona sope: tani Oluwa gbogbo agbaye? * (Musa) sope: Oluwa awon sanmo ati ile ati ohun ti n be ninu awon mejeeji ti e ba je alamodaju. * (Fir'ona) so fun awon ti won n be ni odo re pe: e o wa gbo ni? * (Musa) sope: Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin akoko. * (Fir'aona) sope: dajudaju, ojise ti won ran si yin ti ya were ni. * (Musa) sope: Oluwa ibuyo orun ati ibuwo ati ohun ti n be larin awon mejeeji, ti e ba se laakaye. * (Fir'aona) sope: ti o ba mu Olohun miran leyin mi maa fi o si inu awon elewon}. (Suuratu Ash-shuarau: 23-29).

Igberaga yi ati itanje ati motomoto yio de opin ni igbati ikagara ba de ti agbara si di ohun ti o le, gege bi agbara Fir'aona se de opin ni igba ti igbi-odo bo garu, ti ipokaka iku si de wa ba a, bayi ni o seri si adamo ti o dari re losi ibi ijewo bibe Olohun, asiko naa ki i se asiko abamo, Olohun ti ola Re ga so nipa re bayi pe:

" وجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَائِيلَ الْبَحْرَ فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ وَجُنُودُهُ بَغْياً وَعَدْواً حَتَّى إِذَا أَدْرَكَهُ الْغَرَقُ قَالَ آمَنتُ أَنَّهُ لا إِلِـهَ إِلاَّ الَّذِي آمَنَتْ بِهِ بَنُو إِسْرَائِيلَ وَأَنَاْ مِنَ الْمُسْلِمِينَ {90} آلآنَ وَقَدْ عَصَيْتَ قَبْلُ وَكُنتَ مِنَ الْمُفْسِدِينَ {91} فَالْيَوْمَ نُنَجِّيكَ بِبَدَنِكَ لِتَكُونَ لِمَنْ خَلْفَكَ آيَةً وَإِنَّ كَثِيراً مِّنَ النَّاسِ عَنْ آيَاتِنَا لَغَافِلُونَ {92}" ( يونس:90-92)

{A mu awon omo Isireli la ibudo naa ja, Fir'aona si gba tele won ati awon omo ogun re ni ti abosi ati ikoja ala, titi ti iteri (si inu omi) fi le won ba, o sope: mo ni igbagbo wipe ko si eni ti ijosin tosi ni ododo ayafi Eni ti awon omo isreli gba gbo, emi si n be ninu awon musulumi. * Nje (nisin ni wa gba A gbo)?, o si ti yapa tele, o si wa ninu awon obileje.* A o la ara re (kuro ni bi jijera), ki o le je aami fun awon ti won nbo leyin re, atipe opolopo ninu awon eniyan fonu-fora kuro nibi awon aami Wa}. (Suuratu yunus:90-92).

Tabi ki o je pe itako won ti won ntako ije eru fun Olohun ni ifi aake kori won, ti won o fi wa maa da ododo pada, ti won o si maa ja ni yan paapa nkan ti ntoka si bibe Olohun, won o si maa be ninu anu won, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَجَحَدُوا بِهَا وَاسْتَيْقَنَتْهَا أَنفُسُهُمْ ظُلْماً وَعُلُوّاً فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُفْسِدِينَ " (النمل: 14)

{Won ja awon (aami) naa ni yan niti t'abosi ati igberaga), emi won si mo amodaju pe (ododo ni), idi eleyi, wo bi igbeyin awon obileje se ri}. (Suuratu An-naml:14).

6 - Awon anfani ti ara eni ti n be nibi ijosin fun eniyan abara yato si Olohun, yala anfani yi je ti awujo ni, - gegebi ije adari ninu esin tabi sise oselu ni awujo, won o ma ta awon eniyan ji si awon anfani won, - tabi ki o je anfaani owo ti won o ma gba a lowo awon omo eyin won, gege bi a se nri eyi lodo awon ti won so ite, saare ati awon alagba ijo, Olohun ti ola Re ga sope:

" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ إِنَّ كَثِيراً مِّنَ الأَحْبَارِ وَالرُّهْبَانِ لَيَأْكُلُونَ أَمْوَالَ النَّاسِ بِالْبَاطِلِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ اللّهِ وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلاَ يُنفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللّهِ فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ" (التوبة:34(

{Mope eyin olugbagbo lododo! Dajudaju opolopo ninu awon alagba ijo maa nje owo awon eniyan lona ibaje, won si nseri (awon eniyan) kuro ni oju-onan Olohun, awon ti won ntoju goolu ati fadaka pamo ti won o si na si oju-onan Olohun, fun won ni iro iya eleta-elero}. (Suuratu At-taobah:34).

7 - Igbadun ati idera ti nmuni gbagbe adeda, o si le je pe oga ohun ti o fa ijosin fun eda yato si Olohun ni iberu awon oloro ati awon olola lori titan idekun ti n be lowo won, nitoripe ijosin fun Olohun yio gba opolopo nkan igbadun won lowo won, eyi ti won ri lona sise abosi fun awon eda, bi jije awon owo won lona ibaje, gbigba owo ele, titoju oro-aje pamo, abosi ati bee bee lo, Olohun ti ola Re ga sope;

" وَمَا أَرْسَلْنَا فِي قَرْيَةٍ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتْرَفُوهَا إِنَّا بِمَا أُرْسِلْتُم بِهِ كَافِرُونَ " (سبأ: 34)

 {A o ran olukilo kan si ileko kan ayafi ki awon olola ibe sope: awa se aigbagbo ohun ti e mu wa}. (Suuratu As-sabai:34).

 8 - Aimokan, ti o je okan ninu awon ota eniyan, eyi ti o maa nti i si inu koto anu, won o ma ti itori re da omo eniyan googoo gege bi won se maa nda aguntan, won o si maa lo aimokan won lati mu won maa josin fun elomiran yato si Olohun pelu irorun, Olohun ti ola Re ga sope:

" قُلْ أَفَغَيْرَ اللَّهِ تَأْمُرُونِّي أَعْبُدُ أَيُّهَا الْجَاهِلُونَ " (الزمر:64)

 {Sope: nje elomiran yato si Olohun ni e maa pa mi lase ki nmaa josin fun? Eyin alamokan!}. (Suuratu Az -zumar:64).

 9 - Aile ronu jinle: koni ronu si awon aami ti n be ni odo re, ko si ni ronu si awon nkan ti won aami yi toka si eyi ti yio fi mo ona taara, ti yio si yo kuro ninu anu ati arin tesebose, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّمَا يَخْشَى اللَّهَ مِنْ عِبَادِهِ الْعُلَمَاءُ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ (28)" (فاطر:28)

 {Awon ti paya Olohun ninu awon erusin Re ni awon onimimo, dajudaju Olohun je Oba nla, Alaforijin}. (Suuratu Al-faatir:28).

10 - Awon amunisin ninu awon ota omo eniyan, awon muje-muje, awon amunileru, lati ara fifon olaju ijosin fun elomiran yato si Olohun kaakiri aarin awon eniyan, won o kapa lati mu ero won se, eyi ti o je ti imunileru, iyen ni pe ki won gba laakaye won pelu awon nkan ti ko ni akasi ti yio gbe won jina si otito, ti yio si je ki won maa semi ninu egba adapa iro ati ero buruku, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وقَالَ الْمَلأُ مِن قَوْمِ فِرْعَونَ أَتَذَرُ مُوسَى وَقَوْمَهُ لِيُفْسِدُواْ فِي الأَرْضِ وَيَذَرَكَ وَآلِهَتَكَ قَالَ سَنُقَتِّلُ أَبْنَاءهُمْ وَنَسْتَحْيِـي نِسَاءهُمْ وَإِنَّا فَوْقَهُمْ قَاهِرُونَ" (الأعراف:127)

 (Awon asiwaju ninu ijo Fir'aona sope: nje waa fi Musa ati awon ijo re sile ki won maa se ibaje ni ori'le, ti (Musa) yio si fi o sile ati awon orisa re, o sope: a o maa pa awon omokunrin won, ao si da awon omobinrin won si, dajudaju, awa je alagbara lori won}. (Suuratu Al-A'roof:127).

Sayyid qutub so bayi (ki Olohun se ike Re fun un): "dajudaju apakan ninu awon eniyan ni asiko wa yi mojuto ipada seyin ati aimokan, ti o si foju han ni ona ti o po: Ninu re ni ikoja aala si Olohun ati itako bibe Re, o je adisokan ati iwoye aimokan gege bi aimokan awon eleto ijoba (shuyuiyyah). Ninu re si ni gbigba bibe Olohun gbo ni ona ti ko ye, ati igunri kuro ni ona ijosin ati itele, gege bi aimokan awon oni-orisa ninu awon ara india ati awon miran ti won yato si won, ati gege bi aimokan awon yahudi ati awon nasara (elesin kirisi). Ninu re ni gbigba bibe Olohun gbo ni ona ti o dara, ati sise ijosin fun Un, pelu gigunri nibi iwoye si agboye (ijeri pe kosi elomiran ti ijosin to si lododo ayafi Olohun(Allahu), atipe Anobi Muhammod "ki Olohun se ike ati ola fun un" ojise Olohun nii se), pelu mimu orogun mo Olohun ninu ijosin ati itele, gege bi aimokan apakan awon ti won npe ara won ni musulumi, won lero pe awon ti gba islam, awon si ti ni iroyin islam ni ara ati awon iwo re lenu pe won kan so gbolohun ijeri mejeeji jade lenu lasan, ti won si n se awon ise ijosin, pelu pe won si gbolohun ijeri mejeeji naa gboye, won si gbafa fun imaa josin fun elomiran yato si Olohun.

 

 

Ewu ti n be nibi ijosin fun elomiran yato si Olohun:

 Dajudaju, gbogbo ese eniyan ati asise re ni won o fi ori re jin, won o si mu ojukuro nibe fun un, Olohun ti ola Re ga sope:

 " قُلْ يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ أَسْرَفُوا عَلَى أَنْفُسِهِمْ لا تَقْنَطُوا مِنْ رَحْمَةِ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ جَمِيعاً" (الزمر:53).

 {Sope: mope eyin erusin Mi! awon ti won se abosi fun emi ara won, e ma so ireti nu nibi aanu Olohun, dajudaju, Olohun maa nse aforijin gbogbo ese}. (Suuratu Az-zumar:53).

 Ayafi sise ebo pelu Olohun, oun ni ese ti o tobi julo ti won fi se Olohun ni ori'le, Ko ni mojukuro nibe, Ko si ni se ike eni ti o ba se nise, Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّ اللّهَ لاَ يَغْفِرُ أَن يُشْرَكَ بِهِ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَلِكَ لِمَن يَشَاءُ وَمَن يُشْرِكْ بِاللّهِ فَقَدْ ضَلَّ ضَلاَلاً بَعِيداً" (النساء:116)

{Dajudaju, Olohun ko ni se aforijin fun ki won se ebo pelu Re, Yio si se aforijin ohun ti o ba yato si iye fun eni ti o ba Fe, eni ti o ba se ebo pelu Olohun, dajudaju o ti sonu ni isonu ti o jina}. (Suuratu An-nisai:116).

 Bi o ti wu ki ese po to, ki o wuwo to ni orun eni ti o se e, ti o si pade Olohun lai se ebo kankan pelu Re, yio ri Olohun ni Alaforijin, Onike, gege bi O se so iyen nibp ara Re pe: " Eni ti o ba se daada kan ilopo mewa re yio ma be fun, Maa si tun se alekun, eni ti o ba se aida kan, esan iru re ni yio maa be fun tabi Ki nfi orijin in, eni ti o ba se asise ti o fe se dede ekun ile, leyin naa ti o pade Mi lai se ebo Kankan, Maa se deede iru re fun ni aforijin". (Muslim).

 Oun ni ese ti isipe ise rere ko wulo pelu re fun eni ti o nii, bi o ti wu ki o po to, Olohun ti ola Re ga sope:

"وَقَدِمْنَا إِلَى مَا عَمِلُوا مِنْ عَمَلٍ فَجَعَلْنَاهُ هَبَاء مَّنثُوراً" (الفرقان:23)

 {A wo ohun ti won se nise, A si se ni asedanu ti ko wulo}. (Suuratu Al-fur'qon:23).

 Ikangun eni ti o ba see nipe Olohun yio se ogba idera ni eewo fun, yio si se ni oluse gbere ninu ina, Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَالْمُشْرِكِينَ فِي نَارِ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أُوْلَئِكَ هُمْ شَرُّ الْبَرِيَّةِ " (البينة: 6)

{Dajudaju, awon alaigbagbo ninu awon ara onitira ati awon elebo won o maa be ninu inan jahannamo, won o se gbere ninu re, awon ye ni eda buruku}. (Suuratu Al-bayyinah:6).

Dajudaju, eni ti o ba wo agbaye wa ni oni, yio ri fifonka ima josin fun nkan miran yato si Olohun, ninu ohun ti o bani ninu je ti o si maa nko idamu bani ni wipe wa ri opolopo ninu awon ti won fun ni opo mimo, ti won o maa josin fun eda ti won da bii ti won, gege bi awon elesin kirisi, awon ti won n sope: anobi Isa (maseeh) omo Olohun ni, ati awon yehudi ti won nsope: Uzair omo Olohun ni, Olohun ti ola Re ga sope:

" وقَالَتِ الْيَهُودُ عُزَيْرٌ ابْنُ اللّهِ وَقَالَتْ النَّصَارَى الْمَسِيحُ ابْنُ اللّهِ ذَلِكَ قَوْلُهُم بِأَفْوَاهِهِمْ يُضَاهِؤُونَ قَوْلَ الَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَبْلُ قَاتَلَهُمُ اللّهُ أَنَّى يُؤْفَكُونَ {30} اتَّخَذُواْ أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَاباً مِّن دُونِ اللّهِ وَالْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَمَا أُمِرُواْ إِلاَّ لِيَعْبُدُواْ إِلَـهاً وَاحِداً لاَّ إِلَـهَ إِلاَّ هُوَ سُبْحَانَهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ {31} (التوبة:30-31)

 {Awon yahudi sope: Uzair omo Olohun ni, awon elesin kirisi naa sope: Isa (moseeh) omo Olohun ni, eleyi je oro ti won nso pelu enu won, won nso iru oro awon ti won se aigbagbo siwaju, Olohun sebi le won, bawo ni won se nda adapa iro. * Won mu awon olori won ati awon asiwaju won ati Moseeh omo Maryam ni oluwa yato si Olohun, won o pa won lase nkankan ayafi ki won josin fun Olohun kan soso, ko si olohun miran ayafi Oun naa, mimo Fun un kuro nibi ohun ti won nmu Mo o lorogun}. (Suuratu At-taoba:30-31).

Wa tun ri awon miran ti won o ma josin ti won o si maa se afomo fun igi, okuta ati eranko, koda opo ninu awon ti won pe apemora islam ninu awon musulumi naa maa nse ebo ninu ijosin won, won o maa pe awon oku ninu awon aayo, eni rere ati awon anobi, won o maa ni adisokan pe won ni agbara iru eyi ti ko wa fun eni kan ayafi Olohun nikan, won o maa wa iranlowo lodo won, won o si maa toro gbigbo bukata lodo won ati yiyo won kuro ninu ibanuje, bii wiwo alaisan san, nini omo tabi siso bukata di irorun, won o maa rokirika saare won, won si maa wa alubarika lodo won, won o maa pa eran fun won, won o si maa ni igbenle pe won le se anfaani fun won, won si le ko inira bani, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّن يَدْعُو مِن دُونِ اللَّهِ مَن لَّا يَسْتَجِيبُ لَهُ إِلَى يَومِ الْقِيَامَةِ وَهُمْ عَن دُعَائِهِمْ غَافِلُونَ " (الأحقاف:5)

 {Tani eni ti o sonu to eni ti npe nkan miran yato si Olohun, nkan ti ko le daa lohun titi di ojo ajinde, won si ya afonufora si ipepe won}. (Suuratu Al-Ahqoof:5).

Idi ni ye ti islam fi se leewo gbogbo ohun ti o le je ategun ati ona losi ibi idiro mo nkan miran yato si Olohun, gege bi fifi paro, leke ati eruka yanrin ko ara tabi nkan gun tabi ile, pelu adisokan pe ole fa anfaani, o si le da aburu pada, ati adisokan pe awon irawo ni agbara lori isemi eniyan, ati gbogbo ohun ti o ba jo o, gbogbo re pata wa lati le kodi awon okunfa ti won nmuni losi ibi sise ebo pelu Olohun, ati lati le di gbogbo ona ti o le muni di mo nkan miran tabi gbe okan le leyin Olohun, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ قُلْ أَفَرَأَيْتُم مَّا تَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ إِنْ أَرَادَنِيَ اللَّهُ بِضُرٍّ هَلْ هُنَّ كَاشِفَاتُ ضُرِّهِ أَوْ أَرَادَنِي بِرَحْمَةٍ هَلْ هُنَّ مُمْسِكَاتُ رَحْمَتِهِ قُلْ حَسْبِيَ اللَّهُ عَلَيْهِ يَتَوَكَّلُ الْمُتَوَكِّلُونَ " (الزمر:38)

{Ti o ba biwon pe tani eni ti o da awon sanmo ati ile? Dajudaju, won o sope: Olohun, sope: nje e o ri ohun ti e npe yato si Olohun? Ti Olohun ba gbero inira ka ro mi nje won le ka inira Re kuro? Tabi ti O ba gbero aanu kan ro mi nje won le mu aanu Re dani? Sope: Olohun to mi, Oun ni awon olugbarale o maa gbarale}. (Suuratu Az-zumar:38).

 

 

Paapa ohun ti won njosin fun yato si Olohun:

Dajudaju, gbogbo ohun ti won njosin fun yato si Olohun ninu awon olohun, gbogbo won pata pelu awon ti won njosin fun won won o ni ikapa lati se eda esinsin tabi eera, ki a to wa sope won o ni agbara lati se ohun ti o wu won ni agbaye, tabi ki won mu anfaani wa, tabi ki won da inira pada, idajo yi je idanilagara titi di ojo igbende, Olohun ti ola Re ga sope:

 " يَا أَيُّهَا النَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٌ فَاسْتَمِعُوا لَهُ إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لَن يَخْلُقُوا ذُبَاباً وَلَوِ اجْتَمَعُوا لَهُ وَإِن يَسْلُبْهُمُ الذُّبَابُ شَيْئاً لَّا يَسْتَنقِذُوهُ مِنْهُ ضَعُفَ الطَّالِبُ وَالْمَطْلُوبُ " (الحج: 73)

{Mope eyin eniyan, won fi apejuwe kan lele ni idi eyi ki e teti sii, dajudaju, awon ti e npe yato si Olohun laelae won o le se eda esinsin koda ki won parapo lati daa, ti esinsin ba si mu nkankan jade ni ara won won ole gbaa lowo re, ole ni eni ti ntoro, ole ni nkan ti won ntoro lowo re}. (Suuratu Al-Hajj:73).

Al-Qur'an se alaye paapa awon nkan wonyi ninu opolopo awon aayah re, o si ba awon ti won njosin fun won soro, ti won lero pe owo won ni arisiki won wa, ati iranlowo won, isemi won, alaafia won ati omo won, de bi pe yio hu ibere kale fun won, yio si je ki won kie si ara won nipa anu ati aimokan ti won wa ninu re. Iyato ti o po nbe laarin Adeda ati awon eda, iyato ti o po nbe laarin Adeda, Alagbara,- owo Re ni ikapa gbogbo nkan wa,- ati laarin awon olohun ole ti won da, ti won gbe won kale lori eero buruku ati iro Ni apejuwe, awon ara orikusu ile larubawa ki islam to de, won maa mu orisa won nibi gbogbo nkan, ti o fi de ori nkan ti o yepere ju, apa kan ninu won yio mu dabidun ni orisa re, ti ebi ba pa a, ti ko si ri nkankan ti yio je, (saabe baba Rojau ara iran Utorid) (ki Olohun yonu si ) sope: " a maa njosin fun okuta –ki o to gba islam- ti a ba ri okuta ti o dara ju u lo, a o junu, a o si mu omiran, ti a o ba ri omiran, a o ko iyepe jo, leyin naa a o mu ewure wa, a o si fun wara re si lori, leyin naa a o maa rokirika re" (Al-Bukhaari).

 Awon oni laakaye ati ologbon ninu awon eniyan yi je eniti mo nmo asise won, won o si se atunse adisokan won ni igba ti won ba ti ri ododo. Saabe yi Rooshid omo Abd Robbihi As-silmi (ki Olohun yonu si) lo si odo orisa re siwaju ki o to gba islam gege bi ise re, lati fi nkan rubo fun un, ki o si bere ohun ti o fe lodo re, ni igba ti o de odo re ori kolokolo kan ti nto si lori, o wa duro leni tin se emo, ti nronu, leyin naa o gbo mo anu ti o wa ninu re, o si mo pe inu ibaje ni oun wa, o wa ka awon ile orin kan ti o fi fi ohun ti njosin fun se yeye.

Oluwa ti kolokolo nto si ori re*** eni ti kolokolo ba to si lori ti di eni yepere

 Ti o ba je oluwa ni ko ba ko fun ara re*** ko si ore lara oluwa ti ko le se ohun ti nfe

 Mo mowo mose kuro ni odo orisa ni gbogbo ori ile*** mo si ni igbagbo si Olohun ti O je Olubori (Abu Naheem, ati As-suyuuti lo gba wa ninu tira ti nje "Al-Khasoisul-Kubra).

Eleyi ni laakaye ti o ni alaafia, ati adamo ti o dara, eyi ti o maa nseri si ododo ni igba ti o ba han si. Opo ninu awon aayah Al-Qur'an nba awon laakaye yi soro, won si npaa lase ironu si paapa awon ohun ti won njosin fun yi yato si Olohun, won si n se ni ojukokoro lori sise iwadi, ki o le la kuro nibi aimokan ati ero buruku, won si npepe si ironujinle nipa ijosin fun Olohun nikan. Awon aayah yi si nse ijomitoro oro pelu awon ti won njosin fun nkan miran yato si Olohun, won si n se alaye lile awon olohun won ti won njosin fun, ati ikagara won lati se anfaani fun ara won, dipo ti won o wa se anfaani fun elomiran, won sin le jina fun awon orisa won ti won njosin fun opolopo awon iroyin ti o ye Olohun ti ijosin tosi. Ninu opin aimokan ati iwa omugo ni ki won mu olujosin fun un kan ti ko ni ikapa inira, anfaani, iku, isemi ati igbedide. Olohun ti ola Re ga sope:

" أَيُشْرِكُونَ مَا لاَ يَخْلُقُ شَيْئاً وَهُمْ يُخْلَقُونَ {191} وَلاَ يَسْتَطِيعُونَ لَهُمْ نَصْراً وَلاَ أَنفُسَهُمْ يَنصُرُونَ {192} وَإِن تَدْعُوهُمْ إِلَى الْهُدَى لاَ يَتَّبِعُوكُمْ سَوَاء عَلَيْكُمْ أَدَعَوْتُمُوهُمْ أَمْ أَنتُمْ صَامِتُونَ {193} إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ عِبَادٌ أَمْثَالُكُمْ فَادْعُوهُمْ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ {194} أَلَهُمْ أَرْجُلٌ يَمْشُونَ بِهَا أَمْ لَهُمْ أَيْدٍ يَبْطِشُونَ بِهَا أَمْ لَهُمْ أَعْيُنٌ يُبْصِرُونَ بِهَا أَمْ لَهُمْ آذَانٌ يَسْمَعُونَ بِهَا قُلِ ادْعُواْ شُرَكَاءكُمْ ثُمَّ كِيدُونِ فَلاَ تُنظِرُونِ {195} إِنَّ وَلِيِّـيَ اللّهُ الَّذِي نَزَّلَ الْكِتَابَ وَهُوَ يَتَوَلَّى الصَّالِحِينَ {196} وَالَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِهِ لاَ يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَكُمْ وَلا أَنفُسَهُمْ يَنْصُرُونَ {197} وَإِن تَدْعُوهُمْ إِلَى الْهُدَى لاَ يَسْمَعُواْ وَتَرَاهُمْ يَنظُرُونَ إِلَيْكَ وَهُمْ لاَ يُبْصِرُونَ {198}" (الأعراف:191-198)

{Nje won o maa mu ni orogun ohun ti ko le se eda nkankan, ti o si je pe won se eda won ni? * Won o ni ikapa iranlowo fun won, won o si le ran ara won lowo. * Ti e ba pe won si onamo won o ni tele yin, yala e pe won ni tabi e dake. * Dajudaju awon ti e njosin fun yato si Olohun eru bii ti yin ni won, ni idi eyi, e pe won, ki won si je ipe yin ti e ba je olododo. * Nje won ni awon ese ti won fi nrin? Abi won ni awon owo ti won fi ngba nkan mu? Abi won ni awon oju ti won fi nriran? Abi won ni awon eti ti won fi ngboro? Sope: e pe awon orogun yin, leyin naa ki e da ete fun mi, ki e si mo lomi lara. * Dajudaju Aayo mi ni Olohun ti O so tira kale, Oun ni nmoju to awon eni rere. * Awon ti e npe yato Sii won o ni ikapa iranlowo yin, won o si le ran ara won lowo, ti e ba pe won si onamo won o le gbo, waa ri won ti won o maa wo e, won o si reran}. (Suuratu Al-A'roof:191-198).

Won npe awon oni laakaye ti o ni alaafia si iwoye ati ironujinle nipa awon aami sanmo ati ile ati awon nkan ti Olohun da si inu won ninu awon eda, O si fonka si inu awon mejeeji awon daba ti won o je ki laakaye ti o ni alaafia mo amodaju pe Eni ti o se awon nkan yi ni O ni eto si ijosin lai si orogun fun Un, Olohun ti ola Re ga sope:

 " قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ وَسَلَامٌ عَلَى عِبَادِهِ الَّذِينَ اصْطَفَى آللَّهُ خَيْرٌ أَمَّا يُشْرِكُونَ {59} أَمَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ السَّمَاءِ مَاء فَأَنبَتْنَا بِهِ حَدَائِقَ ذَاتَ بَهْجَةٍ مَّا كَانَ لَكُمْ أَن تُنبِتُوا شَجَرَهَا أَإِلَهٌ مَّعَ اللَّهِ بَلْ هُمْ قَوْمٌ يَعْدِلُونَ {60} أَمَّن جَعَلَ الْأَرْضَ قَرَاراً وَجَعَلَ خِلَالَهَا أَنْهَاراً وَجَعَلَ لَهَا رَوَاسِيَ وَجَعَلَ بَيْنَ الْبَحْرَيْنِ حَاجِزاً أَإِلَهٌ مَّعَ اللَّهِ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ {61} أَمَّن يُجِيبُ الْمُضْطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكْشِفُ السُّوءَ وَيَجْعَلُكُمْ خُلَفَاء الْأَرْضِ أَإِلَهٌ مَّعَ اللَّهِ قَلِيلاً مَّا تَذَكَّرُونَ {62} أَمَّن يَهْدِيكُمْ فِي ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَمَن يُرْسِلُ الرِّيَاحَ بُشْراً بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ أَإِلَهٌ مَّعَ اللَّهِ تَعَالَى اللَّهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ {63} أَمَّن يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَمَن يَرْزُقُكُم مِّنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ أَإِلَهٌ مَّعَ اللَّهِ قُلْ هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ {64} قُل لَّا يَعْلَمُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ الْغَيْبَ إِلَّا اللَّهُ وَمَا يَشْعُرُونَ أَيَّانَ يُبْعَثُونَ {65}" (النمل:59-65)

{Sope: ope fun Olohun, alaafia fun awon erusin Re ti O sa lesa, nje Olohun ni oni ore julo ni tabi ohun ti e nmu lorogun? * Nje tani Eni ti O da awon sanmo ati ile? Ti O si so omi kale fun yin lati sanmo, A si fi mu jade awon ogba oko ti o rewa ti e o ni agbara lati mu igi re jade, nje olohun miran nbe pelu Olohun? Sugbon won je olu morogun (mo Olohun). * Nje tani Eni ti o fi ile rinle? Ti O si fi awon akeremodo sibe, ti o si da awon oke sibe, ti O si fi gaga si aarin awon ibudo meji, nje olohun miran wa pelu Olohun? Sugbon opo ninu won ni won o ni imo. * Nje tani Eni ti O nje ipepe eni ti ara nni nigba ti o ba pe e? ti O si nsipaya aburu kuro, ti O si seyin ni arole ile, nje olohun miran nbe pelu Olohun? O kere ni igba ti e fi n ranti. * Nje tani Eni ti O nfi ona mo yin ninu okunkun ori odan ati inu ibudo? Tani Eni ti nfi ategun ranse ki o maa je iro idunu fun ike Re? Nje olohun miran wa pelu Olohun? Olohun ga tayo ohun ti won nmu mo lorogun. * Nje tani Eni ti O bere dida eda, leyin naa ti Yio tun daa pada? Tani Eni ti n se ije imu lati sanmo ati ile? Nje olohun miran nbe pelu Olohun? Sope: e mu awon arojare yin wa ti e ba je olododo. * Sope: eni kan o mo koko inu awon sanmo ati ile ayafi Olohun, won o si mo asiko ti won o gbe won dide}. (Suurat An-naml:59-65).

Awon aaya Al-Qur'an se alaye paapa awon nkan ti won njosin fun yato si Olohun ni ona meji:

 

Akoko: paapa nkan ti won njosin fun ni aye:

 Awon aaya Al-Qur'an nle jina si awon ohun ti won njosin fun awon iroyin pipe ti o je oranyan ki a rii lara Olohun tooto, ni iwoye si afiwe ti o ba laakaye mu, gege bi ohun ti nbo yi:

Olohun (Oba mimo ti ola Re ga) ni imo nipa gbogbo nkan: Olohun ti ola Re ga sope:

" وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لَا تَأْتِينَا السَّاعَةُ قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتَأْتِيَنَّكُمْ عَالِمِ الْغَيْبِ لَا يَعْزُبُ عَنْهُ مِثْقَالُ ذَرَّةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ وَلَا أَصْغَرُ مِن ذَلِكَ وَلَا أَكْبَرُ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ " (سبأ:3)

 {Awon ti won se aigbagbo si sope: ojo ajinde ko ni de wa bawa, sope: mo fi Oluwa mi Olumo-koko bura! Yio de wa bayin, ohun ti o se deede ere kole bo moO lowo, ninu sanmo tabi ni ile, koda ohun ti o kere ju iye lo tabi ti o tobi julo, ayafi ki o wa ninu tira ti o han}. (Suuratu As-sabai:3).

 - Awon ohun ti won njosin fun yi won kagara ni agbegbe mimo, won o mo nkankan ninu awon bukata awon eniyan ati isesi won, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ عِبَادٌ أَمْثَالُكُمْ فَادْعُوهُمْ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ" (الأعراف:194)

{Dajudaju, awon ti e nke pe yato si Olohun erusin bii ti yin ni won, ni idi eyi, e pe won, ki won si je ipe yin, ti e ba je olododo}. (Suuratu Al-A'roof:194).

 - Olohun (mimo fun un, oba ti ola Re ga julo) ni ikapa ni ori gbogbo nkan, ko si nkankan ti o le ko lagara ninu sanmo tabi ni ori ile, owo Re ni anfaani wa ati inira, Olohun ti ola Re ga sope:

" أَوَلَمْ يَرَوْاْ أَنَّ اللّهَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ قَادِرٌ عَلَى أَن يَخْلُقَ مِثْلَهُمْ وَجَعَلَ لَهُمْ أَجَلاً لاَّ رَيْبَ فِيهِ فَأَبَى الظَّالِمُونَ إَلاَّ كُفُوراً" (الإسراء:99)

 {Se won o mo pe dajudaju Olohun ti O da sanmo ati ile ni agbara lori ki O da iru won? O se gbedeke fun won ti ko ni iyemeji ninu, awon alabosi ko ayafi sise aigbagbo}. (Suuratu Al-Israi:99).

Awon ti won njosin fun yato Si i won kagara ni agbegbe ikapa, won o ni nkankan, won o ni ikapa sise oore fun ara won tabi fun elomiran, bee ni won o le da aburu pada fun ara won tabi elomiran, Olohun ti ola Re ga sope:

" قُلْ أَتَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللّهِ مَا لاَ يَمْلِكُ لَكُمْ ضَرّاً وَلاَ نَفْعاً وَاللّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ {76} " (المائدة:76)

 {Sope: nje e o maa josin fun ohun ti kole ko inira ba yin tabi se yin ni anfaani yato si Olohun, Olohun si ni Olugboro, Olumo}. (Suuratu Al-maidah:76).

 - Olohun Oba mimo ti ola Re ga Oun ni O ni gbogbo nkan, ti E ni ohun ti n be ni awon sanmo ati ile, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَلَلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرضِ وَيَومَ تَقُومُ السَّاعَةُ يَوْمَئِذٍ يَخْسَرُ الْمُبْطِلُونَ " (الجاثية:27)

{Olohun ni O ni awon sanmo ati ile, awon alabosi o se ofo ni ojo ti ijinde o sele}. (Suuratu Al-jaathiyah:27).

Awon ti won njosin fun yi yato si Olohun, won kagara ni agbegbe nini nkan, won o le da nkan ni ninu aye yi, sugbon Olohun ni O ni won, Olohun ti ola Re ga sope:

"قُلِ ادْعُوا الَّذِينَ زَعَمْتُم مِّن دُونِ اللَّهِ لَا يَمْلِكُونَ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ وَمَا لَهُمْ فِيهِمَا مِن شِرْكٍ وَمَا لَهُ مِنْهُم مِّن ظَهِيرٍ" (سبأ: 22)

 {Sope: e pe awon ti e nso yato si Olohun, won o ni ikapa ohunt ti o se deede era ninu awon sanmo ati ile, won o ni ipin Kankan ninu awon mejeeji, kosi si iru Re ninu won}. (Suuratu As-sabai:22).

 - Olohun, Oba mimo ti ola Re ga ni Oluse-eda gbogbo nkan, Olusowon-di-bibe lati ibi aisi, Olohun ti ola Re ga sope:

" ذَلِكُمُ اللّهُ رَبُّكُمْ لا إِلَـهَ إِلاَّ هُوَ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ فَاعْبُدُوهُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ" (الأنعام:102)

{Olohun Oluwa yin ni ye, ko si olohun miran yato Sii, Oluda gbogbo nkan, idi eyi, e se ijosin fun Un, Oun ni Oluso gbogbo nkan}. (Suuratu Al-An'aam:102).

Awon ohun ti won njosin fun yi yato si Olohun won kagara lati da era, Olohun ti ola Re ga sope:

" قُلْ هَلْ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ قُلِ اللّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ فَأَنَّى تُؤْفَكُونَ " (يونس:34)

{Sope: nje o nbe ninu awon olorogun yin eni ti yio bere eda dida leyin naa ti yio tun da pada, sope: Olohun nbere dida eda leyin naa yio tun da pada, tori kini e fi nda adapa iro}. (Suuratu yunus:34).

 - Olohun Oba mimo ti ola Re ga ni nyi agbaye yi pada, Oun si ni Oluseto re ni ibamu si awon eto ti O gbe kale fun lai mehe, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّ رَبَّكُمُ اللّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَى عَلَى الْعَرْشِ يُدَبِّرُ الأَمْرَ مَا مِن شَفِيعٍ إِلاَّ مِن بَعْدِ إِذْنِهِ ذَلِكُمُ اللّهُ رَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ أَفَلاَ تَذَكَّرُونَ " (يونس:3)

{Dajudaju, Oluwa yin ni ti O se eda awon sanmo ati ile fun ojo mefa, leyin naa O rinle si ori aga ola, O nyi awon nkan pada, ko si olusipe kan ayafi leyin iyonda Re, Oluwa yin ni ye, idi eleyi e josin fun Un, nje e o se iranti ni?}. (Suuratu yunus:3).

 Awon ohun ti won njosin fun yato si Olohun won je eniti won ndari, won si kagara lati se idari nkan ninu awon eda Olohun miran, Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِن كُلُّ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ إِلَّا آتِي الرَّحْمَنِ عَبْداً " (مريم:93)

 {Gbogbo ohun ti nbe ninu awon sanmo ati ile won o je nkankan ayafi ki won de wa ba Olohun Ajoke aye ni eru}. (Suuratu maryam:93).

 Olohun Oba mimo ti ola Re ga Oun ni Alarisiki, Alagbara ti o le koko, yio maa da arisiki wa si odo eni ti O ba fe, yio si maa ko fun eni ti o ba wu U, O npese ije –imu gbogbo awon eru Re, O si se awon okunfa ti won o fi de ibe ni irorun fun won, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَكَأَيِّن مِن دَابَّةٍ لَا تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ" (العنكبوت:60(

{Melomelo awon daba ti won o le gbe ije-imu won, Olohun ni nse ije-imu fun won ati eyin naa, Oun si ni Olugboro, Oluriran}. (Suuratu Al-Ankaabut:60).

Awon nkan ti won njosin fun yi yato Si i won kagara ni agbegbe arisiki, won o ni ikapa lati mu ije-imu wa fun yin tabi koo fun yin, Olohun ti ola Re ga sope:

" قُلْ مَن يَرْزُقُكُم مِّنَ السَّمَاءِ وَالأَرْضِ أَمَّن يَمْلِكُ السَّمْعَ والأَبْصَارَ وَمَن يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ الْمَيَّتَ مِنَ الْحَيِّ وَمَن يُدَبِّرُ الأَمْرَ فَسَيَقُولُونَ اللّهُ فَقُلْ أَفَلاَ تَتَّقُونَ " (يونس:31(

{Sope: tani eni tin se ije-imu fun yin ni sanmo ati ni ile? Atipe tani eni ti o ni ikapa igboro ati iriran? Tani eni ti n mu alaye jade lati ara oku ti o si n mu oku jade lati ara alaye? Tani eni ti nyi nkan pada? Won o sope: Olohun ni, idi eyi sope: nje e o ni beru (Olohun)?}. (Suuratu yunus:31).

 - Olohun Oba mimo ti ola Re ga ni Olusemi ni paapa isemi, Ko ni ku be si ni Ko ni tan. Bawo ni Yio se ku ti o si je pe Oun ni O se eda iku, mimo fun Un, Oba ti O da duro ni, kosi ibere fun Un, bee ni kosi ipari fun Un, kosi iru Re, Oun ni alamojuto awon oro awon eda Re, won o le da duro lai Si i, Olohun ti ola Re ga sope:

 " هُوَ الْحَيُّ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ فَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ " (غافر: 65)

{Oun ni Alaaye, kosi olohun miran yato Sii, nitori bee, pe E pelu sise esin ni mimo fun Un, ope fun Olohun Oluwa gbogbo agbaye}. (Suuratu Al-Ghaafir:65).

Awon ohun ti won njosin fun yi yato Si I, yio maa seri si won nkan ti o maa nseri si gbogbo awon eda, bi iku ati titan, won ni ibere bee ni won ni ipari, won o le da se nkan fun ara won, bawo ni won se fe se nkan fun elomiran, won o mo nkan ti won o se fun won, bawo ni won o se mo nkan ti won o se fun elomiran, Olohun ti ola Re ga sope:

 " وَلَا تَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَهاً آخَرَ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ كُلُّ شَيْءٍ هَالِكٌ إِلَّا وَجْهَهُ لَهُ الْحُكْمُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ " (القصص: 88)

{Ma se pe olohun miran mo Olohun, ko si olohun miran yato Sii, gbogbo nkan ni yio parun ayafi oju Re, ti E ni idajo, odo Re si ni e o pada si}. (Suuratu Al-Qasos:88).

 - Olohun Oba mimo ti ola Re ga ni Oluyeni, Olupani, Yio maa ye eni ti O ba fe ninu awon eda Re, ki o le de opin isemi ti Olohun ko sile fun un, Yio si pa eni ti O ba fe ninu awon eda Re ni igba ti won bi (si aye), tabi ni kekere re, Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّ اللّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ يُحْيِـي وَيُمِيتُ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ اللّهِ مِن وَلِيٍّ وَلاَ نَصِيرٍ " (التوبة: 116)

{Dajudaju, Olohun ni O ni ikapa awon sanmo ati ile, Yio maa yeni, Yio si maa pani, ko si oluranlowo ati alaranse kan fun yin leyin Olohun(Allah)}. (Suuratu At-taobah:116).

 Awon ohun ti won njosin fun yi yato Si I, won o ni ikapa nkankan ninu awon nkan yi, koda won o ni ikapa dida titan pada fun ara won, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَاتَّخَذُوا مِن دُونِهِ آلِهَةً لَّا يَخْلُقُونَ شَيْئاً وَهُمْ يُخْلَقُونَ وَلَا يَمْلِكُونَ لِأَنفُسِهِمْ ضَرّاً وَلَا نَفْعاً وَلَا يَمْلِكُونَ مَوْتاً وَلَا حَيَاةً وَلَا نُشُوراً {3}" (الفرقان:3)

{Won mu awon olohun miran ni Olohun yato Sii, won o le se eda nkankan, won si se eda ti won, won o ni ikapa inira tabi anfaani fun ara won, won o ni ikapa iku tabi isemi tabi igbedide}. (Suuratu Al-fur'qoon:3).

 - Olohun Oba mimo ti ola Re ga ni Olupebubu awon arisiki gbogbo awon eda Re, awon ti won nfi oju ri ninu won ati awon ti won o ri, ninu awon eniyan, eranko, eye, kokoro ati beebee lo, Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّ اللَّهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ " (الذاريات: 58)

(Dajudaju, Olohun ni Alarisiki, Alagbara ti o le}. (Suuratu Adh-dhariyaat:58).

 Awon nkan ti won njosin fun yi won kagara lati fun ara won ni onje, bawo ni won se fe fun nkan miran ni onje? Olohun ti ola Re ga sope:

" إِنَّمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ أَوْثَاناً وَتَخْلُقُونَ إِفْكاً إِنَّ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لَا يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقاً فَابْتَغُوا عِندَ اللَّهِ الرِّزْقَ وَاعْبُدُوهُ وَاشْكُرُوا لَهُ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ " (العنكبوت: 17)

{Awon nkan ti e njosin fun un yato si Olohun je orisa, e si n da adapa iro, dajudaju, awon ti e njosin fun yato si Olohun won o ni ikapa arisiski fun yin, idi eyi, e wa ije-imu ni odo Olohun, ki e si se ijosin fun Un, ki e si dupe fun Un, odo Re ni e o pada si}. (Suuratu Al-ankaabuut:17).

 - Olohun Oba mimo ti ola Re ga ni Olugboro, Oluriran, O ngbo ipepe, O si njepe eni ti ara nni, O si gbo awon bukata, O nmu awon ibanuje kuro, O si nwo alaisan san, Olohun ti ola Re ga sope:

" أَمَّن يُجِيبُ الْمُضْطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكْشِفُ السُّوءَ وَيَجْعَلُكُمْ خُلَفَاء الْأَرْضِ أَإِلَهٌ مَّعَ اللَّهِ قَلِيلاً مَّا تَذَكَّرُونَ" (النمل:62)

 {Nje tani eni ti njepe eni ti ara nni ni igba ti o ba ke pe E, ti O si maa nsipaya aburu, ti O si se yin ni arole ile? Nje olohun miran nbe pelu Olohun? o kere ni igba ti e fi n se iranti}. (Suuratu An-naml:62).

 Awon nkan ti won njosin fun yato Si I won o ni ikapa nkankan ninu awon nkan yi, Olohun ti ola Re ga sope:

" لَهُ دَعْوَةُ الْحَقِّ وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِ لاَ يَسْتَجِيبُونَ لَهُم بِشَيْءٍ إِلاَّ كَبَاسِطِ كَفَّيْهِ إِلَى الْمَاء لِيَبْلُغَ فَاهُ وَمَا هُوَ بِبَالِغِهِ وَمَا دُعَاء الْكَافِرِينَ إِلاَّ فِي ضَلاَلٍ " (الرعد:14)

{Oun ni O ni ipepe ododo, awon ti won npe leyin Re won o le jepe won fun nkankan, ayafi gege bi eni ti o na owo re si omi ki o le de enu re, ko le de ibe, ipepe awon alaigbagbo ko je nkankan ayafi anu}. (Suuratu Ar-ra'd:14).

 

Ekeji: paapa nkan ti won njosin fun yato si Olohun ni ojo igbende:

 Olohun so atubotan eni ti o ba njosin tabi tele nkan miran yati Si I, tabi ti o nmu orogun pelu Re. Nitori ki Olohun le tu awon eniyan sile nibi ije eru fun elomiran tabi gbe ara lee yato Si I, Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ حَصَبُ جَهَنَّمَ أَنتُمْ لَهَا وَارِدُونَ {98} لَوْ كَانَ هَؤُلَاء آلِهَةً مَّا وَرَدُوهَا وَكُلٌّ فِيهَا خَالِدُونَ {99} لَهُمْ فِيهَا زَفِيرٌ وَهُمْ فِيهَا لَا يَسْمَعُونَ {100}" ( الأنبياء:99-100)

{Dajudaju, eyin ati ohun ti e njosin fun yato si Olohun je isepe igi ati okuta jahannamo, e o kosi inu re. * Ti o ba sepe awon wonyi je olohun ni won o ba ti kosi inu re, gbogbo won ni won o se gbere (ninu re). * Mimi loke-lole yio maa be fun won ninu re, won o si ni gboro ninu re}. (Suuratu Al-Anbiyaa:99-100).

 - Paapa ohun ti won njosin fun ni asiko iku, Olohun ti ola Re ga sope:

" فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَى عَلَى اللّهِ كَذِباً أَوْ كَذَّبَ بِآيَاتِهِ أُوْلَـئِكَ يَنَالُهُمْ نَصِيبُهُم مِّنَ الْكِتَابِ حَتَّى إِذَا جَاءتْهُمْ رُسُلُنَا يَتَوَفَّوْنَهُمْ قَالُواْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ قَالُواْ ضَلُّواْ عَنَّا وَشَهِدُواْ عَلَى أَنفُسِهِمْ أَنَّهُمْ كَانُواْ كَافِرِينَ {37}" (الأعراف:37)

 {Tani eni ti abosi re to ti eni ti o da adapa iro mo Olohun tabi ti o pea won aami Re ni iro? Awon wonye ni ipin won ninu akosile yio kan won, titi di igba ti awon ojise Wa o de wa bawon, ti won gba emi won, won o sope: nibo ni awon ti npe yato si Olohun wa? Won o sope: a o ri won, won jeri lori ara won pe awon je alaigbagbo}. (Suuratu Al-A'roof:37).

 Paapa ohun ti won njosin fun yato si Olohun ni asiko isiro je ofo ati abamo, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَيَوْمَ يَقُولُ نَادُوا شُرَكَائِيَ الَّذِينَ زَعَمْتُمْ فَدَعَوْهُمْ فَلَمْ يَسْتَجِيبُوا لَهُمْ وَجَعَلْنَا بَيْنَهُم مَّوْبِقاً " (الكهف: 52)

{Ojo ti Yio sope: e pe awon orogun Mi ti e nso, won o pe won sugbon won ni je ipe won, A se aye iparun si aarin won}. (Suuratu Al-kahf:52).

 - Paapa ohun ti won njosin fun yato si Olohun ni asiko isiro je itadiseyin ati imowo-mose (kuro lodo awon ti won njosin fun won), Olohun ti ola Re ga sope:

" وَيَوْمَ نَحْشُرُهُمْ جَمِيعاً ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشْرَكُواْ مَكَانَكُمْ أَنتُمْ وَشُرَكَآؤُكُمْ فَزَيَّلْنَا بَيْنَهُمْ وَقَالَ شُرَكَآؤُهُم مَّا كُنتُمْ إِيَّانَا تَعْبُدُونَ " (يونس: 28)

{Ojo ti A o ko won jo lapapo, leyin naa A o so fun awon ti won mu orogun (pelu Olohun) pe e maa be ni aye yin eyin ati awon orogun yin, A se onpinya larin won, awon orogun won si sope: awa koni e njosin fun}. (Suuratu yunus:28).

 - Paapa ohun ti won njosin fun yato si Olohun ni ojo ikeyin je iba-ara enija ati ota, Olohun ti ola Re ga sope:

واتَّخَذُوا مِن دُونِ اللَّهِ آلِهَةً لِّيَكُونُوا لَهُمْ عِزّاً {81} كَلَّا سَيَكْفُرُونَ بِعِبَادَتِهِمْ وَيَكُونُونَ عَلَيْهِمْ ضِدّاً {82}" (مريم:81-82)

{Won mu awon olohun miran yato si Olohun ki won le je alafeyin fu won, oro ko ri bee o, won o tako won pea won koni won josin fun, won o si ko eyin si won}. (Suuratu Maryam:81-82),

 Paapa ohun ti won njosin fun ni ojo ikeyin ni pe olujosin ati olujosin fun won o maa be ninu ina jahannamo, Olohun ti ola Re ga sope:

 " فَإِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ {161} مَا أَنتُمْ عَلَيْهِ بِفَاتِنِينَ {162} إِلَّا مَنْ هُوَ صَالِ الْجَحِيمِ {163}" (الصافات:161-163)

(Dajudaju, eyin ati ohun ti e njosin fun * E o le ko wahala ba enikankan. * Ayafi eni ti o je ara ina}. (Suuratu As-sofaat:161-163).

 

 

Awon eso ije eru fun Olohun:

 Ije eru fun Olohun maa nyi emi omo eniyan si ibi ise rere, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَتَعَاوَنُواْ عَلَى الْبرِّ وَالتَّقْوَى وَلاَ تَعَاوَنُواْ عَلَى الإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَاتَّقُواْ اللّهَ إِنَّ اللّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ " (المائدة:2(

(E pawopo lori daada ati iberu (Olohun), e mo pawopo lori ese ati ikoja-ala, e beru Olohun, dajudaju, Olohun le koko ni ijeniya}. (Suuratu Al-Maidah:2).

 Ninu awon eso ije eru fun Olohun ni:

 1- Titun enikookan se: o maa nyan ojuse ati iwo laarin awujo, ti enikookan ba mo pe Olohun nri gbogbo ise oun, gbangba re ati koko re, yio maa beru ki Olohun ri oun lori ohun ti O ko fun, tabi ki O ma ri ohun nibi ohun ti O pa lase, Olohun ti ola Re ga sope:

" يَعْلَمُ خَائِنَةَ الْأَعْيُنِ وَمَا تُخْفِي الصُّدُورُ " (غافر:19)

{O mo ijanba ti awon oju se ati ohun ti awon igba-aya pa mo}. (Suuratu Al-Ghaafir:19).

 Iwa enikookan pelu ara re yio dara, Olohun ti ola Re ga sope:

" خُذِ الْعَفْوَ وَأْمُرْ بِالْعُرْفِ وَأَعْرِضْ عَنِ الْجَاهِلِينَ " (الأعراف:199)

{Gba amojukuro mu, pase daada, ki o si seri kuro ni odo awon alaimokan}. (Suuratu Al-A'roof:199).

Yio se atunse Iwa enikookan pelu elomiran, yio si gbe ajose re ga pelu gbogbo ohun ti o rokiri kaa re ninu pelu awon eda, yio fo emi re mo kuro nibi ikoja-ala nibi ife aye, yio wa je olokan ti yio dunnimo mimu awon ase Olohun se, eyi ti n se ni ojukokoro lori sise daada ati ijina si aburu, Olohun ti ola Re ga sope:

" وَقَضَى رَبُّكَ أَلاَّ تَعْبُدُواْ إِلاَّ إِيَّاهُ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً إِمَّا يَبْلُغَنَّ عِندَكَ الْكِبَرَ أَحَدُهُمَا أَوْ كِلاَهُمَا فَلاَ تَقُل لَّهُمَا أُفٍّ وَلاَ تَنْهَرْهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوْلاً كَرِيماً {23} وَاخْفِضْ لَهُمَا جَنَاحَ الذُّلِّ مِنَ الرَّحْمَةِ وَقُل رَّبِّ ارْحَمْهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيراً {24} رَّبُّكُمْ أَعْلَمُ بِمَا فِي نُفُوسِكُمْ إِن تَكُونُواْ صَالِحِينَ فَإِنَّهُ كَانَ لِلأَوَّابِينَ غَفُوراً {25} وَآتِ ذَا الْقُرْبَى حَقَّهُ وَالْمِسْكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ وَلاَ تُبَذِّرْ تَبْذِيراً {26} إِنَّ الْمُبَذِّرِينَ كَانُواْ إِخْوَانَ الشَّيَاطِينِ وَكَانَ الشَّيْطَانُ لِرَبِّهِ كَفُوراً {27} وَإِمَّا تُعْرِضَنَّ عَنْهُمُ ابْتِغَاء رَحْمَةٍ مِّن رَّبِّكَ تَرْجُوهَا فَقُل لَّهُمْ قَوْلاً مَّيْسُوراً {28} وَلاَ تَجْعَلْ يَدَكَ مَغْلُولَةً إِلَى عُنُقِكَ وَلاَ تَبْسُطْهَا كُلَّ الْبَسْطِ فَتَقْعُدَ مَلُوماً مَّحْسُوراً {29} إِنَّ رَبَّكَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ وَيَقْدِرُ إِنَّهُ كَانَ بِعِبَادِهِ خَبِيراً بَصِيراً {30} وَلاَ تَقْتُلُواْ أَوْلادَكُمْ خَشْيَةَ إِمْلاقٍ نَّحْنُ نَرْزُقُهُمْ وَإِيَّاكُم إنَّ قَتْلَهُمْ كَانَ خِطْءاً كَبِيراً {31} وَلاَ تَقْرَبُواْ الزِّنَى إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَسَاء سَبِيلاً {32} وَلاَ تَقْتُلُواْ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللّهُ إِلاَّ بِالحَقِّ وَمَن قُتِلَ مَظْلُوماً فَقَدْ جَعَلْنَا لِوَلِيِّهِ سُلْطَاناً فَلاَ يُسْرِف فِّي الْقَتْلِ إِنَّهُ كَانَ مَنْصُوراً {33} وَلاَ تَقْرَبُواْ مَالَ الْيَتِيمِ إِلاَّ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ حَتَّى يَبْلُغَ أَشُدَّهُ وَأَوْفُواْ بِالْعَهْدِ إِنَّ الْعَهْدَ كَانَ مَسْؤُولاً {34} وَأَوْفُوا الْكَيْلَ إِذا كِلْتُمْ وَزِنُواْ بِالقِسْطَاسِ الْمُسْتَقِيمِ ذَلِكَ خَيْرٌ وَأَحْسَنُ تَأْوِيلاً {35} وَلاَ تَقْفُ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ إِنَّ السَّمْعَ وَالْبَصَرَ وَالْفُؤَادَ كُلُّ أُولـئِكَ كَانَ عَنْهُ مَسْؤُولاً {36} وَلاَ تَمْشِ فِي الأَرْضِ مَرَحاً إِنَّكَ لَن تَخْرِقَ الأَرْضَ وَلَن تَبْلُغَ الْجِبَالَ طُولاً {37} كُلُّ ذَلِكَ كَانَ سَيٍّئُهُ عِنْدَ رَبِّكَ مَكْرُوهاً {38}" (الإسراء:23-38)

{Oluwa re pase pe: e ma josin fun nkan miran ayafi Oun naa, e si se daada si awon obi mejeeji, ti okan ninu awon mejeeji ba de ipo agba lodo re tabi ikinni-keji won ma se si o won, ma si jagbe mo won, so gbolohun aponle fun won. * Re ara nile ni ti aanu fun won, ki o sope: Oluwa se ike awon mejeeji gege bi won se se ike mi ni kekere. * Oluwa yin mo ohun ti n be ni inu awon emi yin, ti e ba je eni rere dajudaju O je Alaforijin fun awon olutuba. * Fun awon alasunmo ni iwo won, ati awon alaini, ati omo-ojuona, ma na ina apa, dajudaju, awon oni ina apa je omo iya esu, esu si je alaigbagbo fun Oluwa re. * Ti o ba yi eyin pada kuro ni odo won nitori aanu Oluwa re ti o nwa, sibesibe so oro ede pelu won. * Ma di owo re mo orun re kukuku (fun ahun), ma si tuu sile tan yanyan (fun ore) ki o ma di eni eebu ti o ma sabamo. * Dajudaju, Oluwa re maa nte arisiki sile fun eni ti O ba wu U, A si maa se ondiwon re (fun eni ti o ba wu U, dajudaju, O je Olumo, Oluri awon erusin Re. * E ma pa awon omo yin nitori iberu osi, Awa ni A nse ije-imu won ati ti yin naa, dajudaju pipa won je ese ti o tobi. * e mo sunmo agbere sise, dajudaju, o je iwa buruku, o si je ona ti ko dara. * E mo pa emi ti Olohun se ni eewo ayafi ni ona eto, eni ti won ba pa ni ona abosi dajudaju A ti fun (Waliyu re) ni agbara, nitorina ko gbodo se ise apa nibi pipani, dajudaju o je eni ti won o ran lowo. * E mo sunmo owo omo-orukan ayafi ni ona ti o dara titi ti yio fi dagba, e mu adehun se, dajudaju, adehun je ohun ti won o beere. * E won osunwon kun ni igba ti e ba won, e si lo eyi ti o se deede ninu osunwon, eleyi ni o ni oore julo, ti o si dara ni ikangun. * Ma se so ohun ti o ko ni imo nipa re, dajudaju igboro, iriran ati awon okan gbogbo awon elewonyi patapata ni won o beere nipa re. * Mo se maa yan rin ni ori'le, dajudaju o le da ile lu, o si le ga to oke. * Gbogbo eyi, aburu je ohun ti Oluwa Re se leewo}. (Suuratu Al-Israi:23-38).

 Olohun ti ola Re gat un sope:

"وَقُل لِّعِبَادِي يَقُولُواْ الَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِنَّ الشَّيْطَانَ يَنزَغُ بَيْنَهُمْ إِنَّ الشَّيْطَانَ كَانَ لِلإِنْسَانِ عَدُوّاً مُّبِيناً" (الإسراء: 53)

{So fun awon erusin mi pe: ki won maa so ohun ti o dara julo, dajudaju, esu yio maa da wahala sile laarin won, dajudaju, awon esu je ota ti o fi oju han fun awon eniyan}. (Suuratu Al-israi:53).

 2 - Sise atunse awujo: o maa njogun atunse fun awujo, nitoripe nbe ninu re awon ofin ti nmojuto siso emi, owo, omoluwabi, laakaye ati idile.

* Olohun ti ola Re ga so nipa siso emi ati ara:

"وَكَتَبْنَا عَلَيْهِمْ فِيهَا أَنَّ النَّفْسَ بِالنَّفْسِ وَالْعَيْنَ بِالْعَيْنِ وَالأَنفَ بِالأَنفِ وَالأُذُنَ بِالأُذُنِ وَالسِّنَّ بِالسِّنِّ وَالْجُرُوحَ قِصَاصٌ فَمَن تَصَدَّقَ بِهِ فَهُوَ كَفَّارَةٌ لَّهُ وَمَن لَّمْ يَحْكُم بِمَا أنزَلَ اللّهُ فَأُوْلَـئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ" (المائدة:45)

{A se ni oranyan fun won ninu re (At-taoraat) pe emi yio je iparo fun emi, oju fun oju, imu fun imun, eti fun eti, eyin fun eyin, igbesan si nbe fun ogbe, e ni ti o ba fi se saara yio je iha ese kuro fun un, eni ti ko ba dajo pelu ohun ti Olohun so kale awon iye ni alabosi}. (Suuratu Al-Maaidah:45).

* Olohun ti ola Re ga so nipa siso owo:

"وَالسَّارِقُ وَالسَّارِقَةُ فَاقْطَعُواْ أَيْدِيَهُمَا جَزَاء بِمَا كَسَبَا نَكَالاً مِّنَ اللّهِ وَاللّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ" (المائدة:38)

{Ole lokunrin ati lobinrin e ge awon owo awon mejeeji, ki o je esan fun ise ti won se, ki o si je ijeniya lati odo Olohun, Olohun ni Oba'nla Ojogbon}. (Suuratu Al-Maaidah:38).

* Olohun so nipa siso omoluwabi nibi agbere:

"الزَّانِيَةُ وَالزَّانِي فَاجْلِدُوا كُلَّ وَاحِدٍ مِّنْهُمَا مِئَةَ جَلْدَةٍ وَلَا تَأْخُذْكُم بِهِمَا رَأْفَةٌ فِي دِينِ اللَّهِ إِن كُنتُمْ تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَلْيَشْهَدْ عَذَابَهُمَا طَائِفَةٌ مِّنَ الْمُؤْمِنِينَ" (النور:2)

{Alagbere lokunrin ati lobinrin e nan ikinni-keji won ni egba ogorun, aanu ko gbodo se yin nipa won lati tele ase Olohun, ti e ba ni igbagbo nipa Olohun ati ojo ikeyin, ki awon apakan ninu awon mumini ganni iya won}. (Suuratu An-nuur:2).

 - Olohun ti ola Re ga so nipa siso omoluwabi nibi adapa iro sinan:

"وَالَّذِينَ يَرْمُونَ الْمُحْصَنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَأْتُوا بِأَرْبَعَةِ شُهَدَاء فَاجْلِدُوهُمْ ثَمَانِينَ جَلْدَةً وَلَا تَقْبَلُوا لَهُمْ شَهَادَةً أَبَداً وَأُوْلَئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ" (النور:4)

{Awon ti won nju iro mo awon enimimo, leyin naa ti won o mu awon eleri merin wa, e nan won ni egba ogorin, e o si gbodo gba eri kankan je fun won lailai, awon wonyi si ni onise-ibi}. (Suuratu An-nuur:4).

* Olohun ti ola Re ga so nipa siso laakaye:

"يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ قُلْ فِيهِمَا إِثْمٌ كَبِيرٌ وَمَنَافِعُ لِلنَّاسِ وَإِثْمُهُمَا أَكْبَرُ مِن نَّفْعِهِمَا وَيَسْأَلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَ قُلِ الْعَفْوَ كَذَلِكَ يُبيِّنُ اللّهُ لَكُمُ الآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَتَفَكَّرُونَ" (البقرة:219)

{Won o bi o nipa oti ati tete tita, sope: ese ti o tobi nbe nibi awon mejeeji fun awon eniyan ati awon anfaani, ese won si tobi ju anfaani won lo, won o si bi o pe: ki ni won o maa naa? Sope: amojukuro, baye ni Olohun yio maa se alaye awon aami fun yin, ki e le ronu}. (Suuratu Al-baqorah:219).

 *Olohun ti ola Re ga so nipa siso awon aromodomo:

"وَإِذَا تَوَلَّى سَعَى فِي الأَرْضِ لِيُفْسِدَ فِيِهَا وَيُهْلِكَ الْحَرْثَ وَالنَّسْلَ وَاللّهُ لاَ يُحِبُّ الفَسَادَ" (البقرة:205)

{Ti o ba yi eyin pada yio maa lo ni ori'le ki o se ibaje ni be, yio si ko iparun ba oko ati omo, Olohun ko nife ibaje}. (Suuratu Al-baqorah:205).

 3 - Fifi eto si ajose ilu si ilu ati abagbepo pelu daada: Awon eda eru ni won je fun Olohun, eni ti o josin fun Un ati eni to ko josin fu Un, O pase sise daada si won ni aye, isiro won si dowo Olohun ni ojo ikeyin, Olohun ti ola Re ga sope:

 "يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوباً وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ" (الحجرات:13)

{Mope eyin eniyan! Dajudaju, A se eda yin ni tako-tabo, A si seyin ni ijo-ijo, ati iran-iran ki e le se iyato laarin ara yin, dajudaju, eni aponle ju ninu yin ni oluberu (Olohun) ju ninu yin, dajudaju, Olohun ni Onimimo, Olufunni-niro" (Suuratu Al-Hujuroot:13).

Olohun Oba mimo ti ola Re ga ko gbe ojise Re anobi Muhammad (ki Olohun se ike ati ola Fun un) dide ayafi ki o je aanu fun gbogbo awon eniyan, eni ti o tele e ati eni ti ko tele e, ohun ti Olohun se ni adehun ninu esan nbe fun eni ti o ba tele e, won o ni se abosi fun eni ti ko tele e nipa esan re, Olohun ti ola Re ga sope:

"وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَالَمِينَ" (الأنبياء:107)

{A o ran o nise ayafi ki o le je aanu fun gbogbo agbaye}. (Suuratu Al-Anbiyaa:107).

Eleyi ni ipepe re, eleyi si ni esin re ti Olohun fi ran an, ipepe sibi ije eru fun Olohun pelu pelepele ati oro ti o dara, Olohun ti ola Re ga sope:

"ادْعُ إِلِى سَبِيلِ رَبِّكَ بِالْحِكْمَةِ وَالْمَوْعِظَةِ الْحَسَنَةِ وَجَادِلْهُم بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ" (النحل: 125)

{Pepe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ati isiti ti o dara, ki o si ba won jiyan ni ona ti dara julo, dajudaju, Oluwa re ni O ni imo nipa eni ti o sonu kuro ni oju ona Re, Oun ni O si mo awon olumona}. (Suuratu An-nahl:125).

 Ije eru re fun Olohun ati titele ofin Re o sodi tulaasi ki o je oni deede pelu gbogbo nkan, pelu emi re ati pelu gbogbo ohun ti o rokirika re ninu awon eda Olohun, titi ti o fi de ori sise daada si awon eranko. Obinrin kan wo ina lati ara olongbo kan ti o so mole, ko fun ni onje, ko si tu sile ki o je ninu awon kokoro ori'le.

Asewo kan ninu awon omo isireli wo ogba idera lati ara fifun aja kan ni omi mu ti o nje erupe fun ongbe, won si fi ori jin arakunrin kan ti o mu igi elegun kan ti o nse awon eniyan ni aida kuro ni oju ona, gege bi ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) se mu iro wa nipa eleyi, ati deede pelu eni ti o nmu o ni ota, ko si abosi, a mo ajose ti o da ati iwa ti o rewa, Olohun ti ola Re ga sope:

 "قُلْ أَمَرَ رَبِّي بِالْقِسْطِ وَأَقِيمُواْ وُجُوهَكُمْ عِندَ كُلِّ مَسْجِدٍ وَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ كَمَا بَدَأَكُمْ تَعُودُونَ" (الأعراف:29)

{Sope: Oluwa mi pase deede, e koju si ibu dajuko (ka'aba) ni gbogbo mosalasi, ki e pe E ti e o se esin ni mimo fun Un, gege bi O se bere yin naa ni e o pada si}. (Suuratu Al-A'roof:29).

Ni isinyi a o so die ninu awon aaya ti won nso nipa abagbe daada:

* Sise rere ati ihu iwa daada si won: Olohun ti ola Re ga sope:

" لَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ أَن تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ {8}" (الممتحنة:8)

{Olohun ko ko fun lati se daada ati deede si awon ti won o bayin ja nipa esin, ti won o si le yin jade ni ilu yin, dajudaju, Olohun nife awon onideede}. (Suuratu Al-mumtahinah:8).

* Fifun won ni ifokanbale ati aabo: Olohun ti ola Re ga sope:

"وَإِنْ أَحَدٌ مِّنَ الْمُشْرِكِينَ اسْتَجَارَكَ فَأَجِرْهُ حَتَّى يَسْمَعَ كَلاَمَ اللّهِ ثُمَّ أَبْلِغْهُ مَأْمَنَهُ ذَلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لاَّ يَعْلَمُونَ" (التوبة:6)

{Ti enikan ninu awon elebo ba wa idaabobo re daabo bo o titi ti yio fi gbo oro Olohun, leyin naa muu de aye abo re, iye nipe won je ijo alaimo" (Suuratu At-taobah:6).

 - Aini tanwonje tabi jamba won: Olohun ti ola Re ga sope:

 "وَإِمَّا تَخَافَنَّ مِن قَوْمٍ خِيَانَةً فَانبِذْ إِلَيْهِمْ عَلَى سَوَاء إِنَّ اللّهَ لاَ يُحِبُّ الخَائِنِينَ" (الأنفال:58)

{Ti o ba nberu ijanba ni ara awon ijo kan, fi mo won pe o ba won se, ti e o si jo mo sii, dajudaju, Olohun ko nife awon onitanje" (Suuratu Al-anfaal:58).

* Dida awon dukia won (ti won toju si yin lodo) pada: Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّ اللّهَ يَأْمُرُكُمْ أَن تُؤدُّواْ الأَمَانَاتِ إِلَى أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُم بَيْنَ النَّاسِ أَن تَحْكُمُواْ بِالْعَدْلِ إِنَّ اللّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُم بِهِ إِنَّ اللّهَ كَانَ سَمِيعاً بَصِيراً" (النساء:58)

{Dajudaju, Olohun npayin lase pe ki e da awon dukia pada si odo awon ara re, ni igba ti e ba dajo laarin awon eniyan ki e dajo pelu deede, dajudaju, mondala ohun ti Olohun nse yin ni ikilo re, dajudaju, Olohun je Olugboro, Oluriran" (Suuratu An-nisai:58).

* Pipe adehun won: Olohun ti ola Re ga sope:

"إِلاَّ الَّذِينَ عَاهَدتُّم مِّنَ الْمُشْرِكِينَ ثُمَّ لَمْ يَنقُصُوكُمْ شَيْئاً وَلَمْ يُظَاهِرُواْ عَلَيْكُمْ أَحَداً فَأَتِمُّواْ إِلَيْهِمْ عَهْدَهُمْ إِلَى مُدَّتِهِمْ إِنَّ اللّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ" (التوبة:4)

{Ayafi awon ti e se adehun fun ninu awon elebo, leyin naa ti won o din yin ku ni nkankan, ti won o si ran (ota) Kankan lowo lori yin, idi eyi, e pe adehun won fun won di opin asiko won ti won da, dajudaju, Olohun nnife awon oluberu (Olohun)}. (Suuratu At-taobah:4).

* Sise deede pelu won ati aise abosi si won: Olohun ti ola Re ga sope:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ كُونُواْ قَوَّامِينَ لِلّهِ شُهَدَاء بِالْقِسْطِ وَلاَ يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ عَلَى أَلاَّ تَعْدِلُواْ اعْدِلُواْ هُوَ أَقْرَبُ لِلتَّقْوَى وَاتَّقُواْ اللّهَ إِنَّ اللّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ" (المائدة:8)

{Mope eyin olugbagbo ododo! E je oluduro ti Olohun, olujeri pelu deede, e mo je ki ikorira awon ijo kan mu yin se aise deede, e se deede, oun ni o fi nsunmo iberu Olohun, e beru Olohun., dajudaju, Olohun je Olufunini –iro ohun ti e ba se ni ise" (Suuratu Al-Maaidah:8).

* Imo se won ni suta: Olohun ti ola Re ga sope:

"وَقَاتِلُواْ فِي سَبِيلِ اللّهِ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَكُمْ وَلاَ تَعْتَدُواْ إِنَّ اللّهَ لاَ يُحِبِّ الْمُعْتَدِينَ" (البقرة:190)

{E baa won ja ni oju ona Olohun awon ti won nba yin ja, e mo koja aala, dajudaju, Olohun ko nife awon olukoja aala}. (Suuratu Al-Baqorah:190).

* Bi ba won lo pelu alaafia: Olohun ti ola Re ga sope:

 "وَإِن جَنَحُواْ لِلسَّلْمِ فَاجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى اللّهِ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ" (الأنفال:61)

{Ti won ba seri (kuro ni bi ogun jija) iwo naa fi sile fun won, ki o sig be ara le Olohun, dajudaju, Oun ni Olugboro, Onimimo}. (Suuratu al-Anfaal:61)

4 - Bibori wiwonkoko ojukokoro awon eniyan eyi ti o je ti eranko, Olohun ti ola Re ga sope:

"قُلْ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَالإِثْمَ وَالْبَغْيَ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَأَن تُشْرِكُواْ بِاللّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَاناً وَأَن تَقُولُواْ عَلَى اللّهِ مَا لاَ تَعْلَمُونَ" (الأعراف:33)

{Sope: dajudaju, Oluwa mi se aburu leewo, eyi ti o han ninu re ati eyi ti o pamo, ati ese ati tenbelekun ni onan ti ko leto, ati ki e mu mo Olohun ohun ti ko fi eri re lele, ati ki e so ohun ti e o mo nipa Olohun}. (Suuratu Al-A'roof:33).

5 - O maa njogun irankan daada ati aba daada pelu Olohun, o si maa ngbeni jina si irankan aburu eyi ti o maa nko ole ba eero, ti o si maa npa agbokante. Bayi ni emi o fi bale, ti yio si yonu si idajo Re ati kadara Re, nitoripe o mo pe ohun ti o ba kadara oore ni, koda ki ode re yato si bee, yio si mo gbadun isemi, ko si ni ri ni isemi yi ayafi awon nkan daada. Olohun ti ola Re ga sope:

"فَإِنَّ مَعَ الْعُسْرِ يُسْراً {5} إِنَّ مَعَ الْعُسْرِ يُسْراً {6}" (الشرح:5-6)

{Dajudaju, idera nbe pelu inira, dajudaju, idera nbe pelu inira}. (Suuratu Ash-sharh:5-6).

5 - O maa nla eniyan kuro nibi adapa iro, ati eero buruku ti o maa so eniyan po mo awon nkan ti won njosin fun ti won o ni anfaani tabi inira. Ibraheem baba awon anobi Olohun se alaye paapa eleyi fun awon ijo re ni ona ti yio jeki won ronu si paapa nkan ti won njosin fun. Olohun ti ola Re ga so bayi nipa re pe:

"وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ إِبْرَاهِيمَ {69} إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا تَعْبُدُونَ {70} قَالُوا نَعْبُدُ أَصْنَاماً فَنَظَلُّ لَهَا عَاكِفِينَ {71} قَالَ هَلْ يَسْمَعُونَكُمْ إِذْ تَدْعُونَ {72} أَوْ يَنفَعُونَكُمْ أَوْ يَضُرُّونَ {73} قَالُوا بَلْ وَجَدْنَا آبَاءنَا كَذَلِكَ يَفْعَلُونَ {74} قَالَ أَفَرَأَيْتُم مَّا كُنتُمْ تَعْبُدُونَ {75} أَنتُمْ وَآبَاؤُكُمُ الْأَقْدَمُونَ {76} فَإِنَّهُمْ عَدُوٌّ لِّي إِلَّا رَبَّ الْعَالَمِينَ {77} الَّذِي خَلَقَنِي فَهُوَ يَهْدِينِ {78} وَالَّذِي هُوَ يُطْعِمُنِي وَيَسْقِينِ {79} وَإِذَا مَرِضْتُ فَهُوَ يَشْفِينِ {80} وَالَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحْيِينِ {81} وَالَّذِي أَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لِي خَطِيئَتِي يَوْمَ الدِّينِ {82}" (الشعراء:69-82)

{Ka iro nipa Ibraheem fun won. * Nigba ti o so fun baba re ati awon ijo re pe: kini e njosin fun? * Won sope: awa njosin fun awon orisa kan ti a nteri ba fun won. * O sope: nje won ngbo yin nigba ti e ba npe won? * Tabi won ti e le se yin ni anfaani tabi inira? * Won sope: rara o, bayi ni a ri awon baba wa ti won nse. * O sope: nje eyin se akiyesi nipa ohun ti e nsin. * Eyin ati awon baba yin ti won ti siwaju. * Dajudaju won je ota fun mi ayafi Oluwa gbogbo agbaye. * Eni ti o se eda mi ti yio si fi ona ma mi. * Eni ti o je pe Oun ni nfun mi ni onje ti o si n fun mi ni mimu. * Ti mo ba saisan Oun ni yio wo mi san. * Eni ti yio pa mi leyin naa ti yio tun ji mi. * Eni ti mo nse agbokanle ki O fori awon asise mi jin mi ni ojo esan}. (Suuratu Ash-shuarai:69-82).

 6 - O maa nla eniyan kuro nibi imuni leru awon ofin ati eto awon eniyan eyi ti won gbe kale lati ri awon anfaani ti ara eni, tabi ti agbegbe, tabi ti orile ede eyi ti won maa nmu awon eniyan leru lati ara re. Olohun ti ola Re ga sope:

 " قُلْ أَغَيْرَ اللّهِ أَتَّخِذُ وَلِيّاً فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَهُوَ يُطْعِمُ وَلاَ يُطْعَمُ قُلْ إِنِّيَ أُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ أَوَّلَ مَنْ أَسْلَمَ وَلاَ تَكُونَنَّ مِنَ الْمُشْرِكَينَ " (الأنعام:14)

{Sope: nje elomiran yato si Olohun Oluda awon sanmo ati ile ni maa mu ni aayo? Oun ni nfunni ni onje won kii fun Un ni onje, sope: dajudaju, won pa mi lase pe ki n je akoko eni ti yio gba islam, mo wa pelu awon elebo}. (Suuratu Al-An'aam:14).

8 - fifun emi eru ni onje amodaju, ati igbekele Olohun ni ona ti o dara, yio wa mo bori awon ilekoko ati awon adanwo pelu ohun ti ije eru fun Olohun yio ma ju si ni okan ninu ifokantan (Olohun), awon eero koni pofo, beeni awon ireti ko ni jaa. Anobi Musa (eyi ti o lola ninu ike ati ola Olohun ki o maa ba) leyin igba ti o sa pelu awon ijo re kuro nibi ijeniya Firaonan ati awon omoleyin re, awon ti won npa awon omokunrin won ti won si fi awon omobinrin won sile, ti o si dina mo won pelu awon omo-ogun re ti won po, ati pelu okan re ti o kun fun keeta ati ibinu lori won ti ibudo nla wa nbe ni iwaju Musa ati awon ijo re, kosi abayo fun won, bee ni kosi ona, Fir'aona ati awon omo-ogun re si n be ni eyin won, kosi oluranlowo, kosi alaranse, awon ijo Musa mo amodaju pe iparun ti de, won so pe:

 " إِنَّا لَمُدْرَكُونَ (61) " (الشعراء:61)

{Dajudaju owo ti ba wa}. (Suuratu Ash-shuarooi:61).

Musa so fun won pelu ogbokanle ninu Olohun ti ododo ati amodaju ti o dara pe: ko ri bee, koda Olohun yio se eero alabosi ni ofo, yio si o pa re ati awon ijo re, Olohun ko ni dojuti eni ti o ba gbokan le E, ti o si da aba daada pelu Re. Olohun ti ola Re ga sope:

 "فأتْبَعُوهُم مُّشْرِقِينَ {60} فَلَمَّا تَرَاءى الْجَمْعَانِ قَالَ أَصْحَابُ مُوسَى إِنَّا لَمُدْرَكُونَ {61} قَالَ كَلَّا إِنَّ مَعِيَ رَبِّي سَيَهْدِينِ {62} فَأَوْحَيْنَا إِلَى مُوسَى أَنِ اضْرِب بِّعَصَاكَ الْبَحْرَ فَانفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرْقٍ كَالطَّوْدِ الْعَظِيمِ {63} وَأَزْلَفْنَا ثَمَّ الْآخَرِينَ {64} وَأَنجَيْنَا مُوسَى وَمَن مَّعَهُ أَجْمَعِينَ {65} ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ {66} إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ {67}" ( الشعراء:60-67)

(Won si gba tele won ni iyaleta. * Nigba ti awon ijo mejeeji fi oju kan ara won, awon ijo Musa sope: dajudaju owo ti te wa. * O sope: kori be, dajudaju Oluwa mi nbe pelu mi yio fi ona mo mi. * A ranse si Musa pe fi popa owo re lu ibudo, o si pin, ipin kookan si da bi oke nla. * A si sun awon ijo jeji mo ibe. * A la Musa ati awon ti won n be pelu re ni apapo. * leyin naa A te awon ijo keji ri. * Dajudaju aami kan nbe nibi eleyi, opo ninu won o je olugbagbo ododo}. (Suuratu Ash-shuarooi:60-67).

 9 - Asiri orire emi ati ifokanbale okan nbe nibi ona igbagbo nipa idajo ati kadara, titi ti eru yio fi mo pe ohun ti o ba sele si i ko le tase re, ati pe ohun ti o tase re kole sele si i, gege bi ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o maa ba) se so iro nipa eyi pelu oro re pe: "lo mo pe dajudaju ti awon ijo ba kojo lori ati se o ni anfaani kan, won o le se o ni anfaani ayafi nkan ti Olohun ti ko sile fun o, ti won ba si kojo lori ati fi inira kan kan o, won o le fi inira kan o ayafi nkan ti Olohun ti ko sile lori re". (At-tirmidhi).

 Nigba ti eniyan ba ti nni igbanmo eleyi, ti o si ni amodaju pe gbogbo nkan owo Olohun ni o wa, atipe dajudaju nkankan ko le sele ni aye yi ayafi ohun ti Olohun kadara re ti O si da lejo, emi re yio bale, yio si sise gege bi O se pase, yio si yonu si ohun ti O pin. Olohun ti ola Re ga sope:

"مَا أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ وَمَن يُؤْمِن بِاللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ" (التغابن:11)

{Adanwo kan kole sele ayafi pelu iyonda Olohun, eni ti o ba ngba Olohun gbo Yio se imonan okan re, Olohun je Olumo nipa gbogbo nkan}. (Suuratu At-taghoobun:11).

Yio se afiti oro re si odo Olohun, koni paya, koni binu si ohun ti nsele ti okan ko, abayo le wa lati inu adanwo, melomelo adanwo ti paapa re je oore ati idekun, Olohun mo, eyin si je alaimo. At-tobaraani so ninu tafsir tAt-tabaraani wipe Ibn Abbas (ki Olohun yonu si i) sope: " mo nbe leyin ojise Olohun (ki Olohun se ike ati ola fun) lori nkan gun, o wa sope: ire omo Abbas! Yonu si Olohun pelu ohun ti O kadara, koda ki o yato si ife re, nitoripe won ti fi rinle ninu tira Olohun. Mo sope: ire ojise Olohun! nibo ni? Mo ti ka Al –Qur'an! O sope: ninu oro Re:

" وَعَسَى أَنْ تَكْرَهُوا شَيْئًا وَهُوَ خَيْرٌ لَكُمْ وَعَسَى أَنْ تُحِبُّوا شَيْئًا وَهُوَ شَرٌّ لَكُمْ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ" (البقرة: 216)

{O se se ki e korira nkankan ti o si je pe oore ni fun yin, o se se ki e nife nkankan ti o si je pe aburu ni fun yin, Olohun mo eyin o si mo}. (Suuratu Al-Baqorah:216)" (tafseer At-tabaraani).

 10 - fifi ara da eta-ero ati sise suuru lori re: Ije eru fun Olohun maa njogun adun si inu okan, eni kan ko le ni igbonmo re ayafi eni ti igbagbo re ba je ododo nibi ije eru re, yio mu gbagbe gbogbo eta-ero aye yi. Awon opidan Fir'aona ti won de lati wa ba Musa figagbaga pelu idan won, nigba ti won ri otito aami re, igbagbo sokale si inu okan won, won si jewo ije eru fun Olohun, Fir'aona pase ijewon niya siwaju ki o to pa won, won o deyin leyin igbagbo won, won se suuru lori re, gege bi Olohun se so iro nipa eleyi ninu oro Re pe:

 " فَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سُجَّداً قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ هَارُونَ وَمُوسَى {70} قَالَ آمَنتُمْ لَهُ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ إِنَّهُ لَكَبِيرُكُمُ الَّذِي عَلَّمَكُمُ السِّحْرَ فَلَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُم مِّنْ خِلَافٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ فِي جُذُوعِ النَّخْلِ وَلَتَعْلَمُنَّ أَيُّنَا أَشَدُّ عَذَاباً وَأَبْقَى {71} قَالُوا لَن نُّؤْثِرَكَ عَلَى مَا جَاءنَا مِنَ الْبَيِّنَاتِ وَالَّذِي فَطَرَنَا فَاقْضِ مَا أَنتَ قَاضٍ إِنَّمَا تَقْضِي هَذِهِ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا {72} إِنَّا آمَنَّا بِرَبِّنَا لِيَغْفِرَ لَنَا خَطَايَانَا وَمَا أَكْرَهْتَنَا عَلَيْهِ مِنَ السِّحْرِ وَاللَّهُ خَيْرٌ وَأَبْقَى {73} إِنَّهُ مَن يَأْتِ رَبَّهُ مُجْرِماً فَإِنَّ لَهُ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحْيى {74}" ( طه:70-74)

{Awon opidan si wo lule fun iforikanle, won sope: a ni igbagbo nipa Oluwa Haruna ati Musa. * O sope: e gba fun siwaju ki nto yonda fun yin, dajudaju o je oga yin ti o ko yin ni idan. * Dajudaju maa ge awon owo yin ati awon ese yin lodi-lodi, ma si kan yin mo iti igi dabidun, dajudaju e o mo eni ti iya re le ju ti yio si seku. * Won sope: a o ni gbe ola fun o lori ohun ti o de wa bawa ninu awon aami, afi eni ti o da wa bura! Se ohun ti o fe se, dajudaju agbara idajo aye yi lasan ni o ni. * Dajudaju a wa ni igbagbo nipa Oluwa wa ki O le fi ori awon asise wa jin wa, ati ohun ti o tulasi wa lori re ninu idan, Olohun ni O loore julo ti Yio si seku. * Dajudaju eni ti o ba de wa ba Oluwa re ni alaburu, dajudaju ina jahannamo nbe fun un, ko ni ku ninu re, ko si ni ye}. (Suuratu Toha:70-74).

11 - Bibi sise akiyesi ara eni si inu okan eru, eyi ti o je pe lati ibe ni eru o ti ma se akiyesi awon ise re ati awon oro re, ati lilo-bibo re laatara sise igbonmo oro Olohun ti o sope:

"يَعْلَمُ خَائِنَةَ الْأَعْيُنِ وَمَا تُخْفِي الصُّدُورُ" (غافر:19)

{O mo ijanba ti awon oju se ati ohun ti awon igba-aya pa mo}. (Suuratu Al-Ghaafir:19).

Wa a ri ti yio maa se ojukokoro lori pe ki Olohun maa se afeku oun nibi ohun ti O pa lase, ki O si maa ri oun nibi ohun ti O ko fun un, nitoripe yio maa ni igbonmo iso Olohun lori re, ati giganni Re lori awon ise re, yio wa se ojukokoro lati pe awon ohun ti O fi okan tan lori re, ati ohun ti awon eniyan fi okan tan, yato si siso ti ode, eyi ti eniyan yio fe k'eyin si nigba ti iso ti ode ba pamo, tabi ti o gbagbera tabi ti o ba ti le, ni apejuwe, saka yiyo ninu islam, musulumi yio je ara re nipa lati yoo, koda yio se iwadi nipa eni ti o ni eto si i, yio fun un ti inu re yio si dun si i,yato si awon owo ori eyi ti won se ni oranyan lori won, won o mo wa orisirisi ona lati le ma san, pelu eru tabi iro tabi owo oya, ati gbogbo ohun ti o joo ninu awon iwa eebu.

12 - Iwosan fun awon adanwo eru ati idunnu fun emi re: Pelu ije eru re ni yio fi ri abayori fun gbogbo awon adanwo re, nipa pipasofo pelu Olohun re, ati mimu awon ase re se ni awon ipo yi. Olohun ti ola Re ga sope:

" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ اسْتَعِينُواْ بِالصَّبْرِ وَالصَّلاَةِ إِنَّ اللّهَ مَعَ الصَّابِرِينَ " (البقرة:153)

{Mope eyin olugbagbo ododo! E wa iranlowo pelu suuru ati irun kiki, dajudaju, Olohun nbe pelu awon onisuuru}. (Suuratu Al-Baqorah:153).

Olohun ti ola Re ga tun sope:

"ولَنَبْلُوَنَّكُمْ بِشَيْءٍ مِّنَ الْخَوفْ وَالْجُوعِ وَنَقْصٍ مِّنَ الأَمَوَالِ وَالأنفُسِ وَالثَّمَرَاتِ وَبَشِّرِ الصَّابِرِينَ {155} الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُم مُّصِيبَةٌ قَالُواْ إِنَّا لِلّهِ وَإِنَّـا إِلَيْهِ رَاجِعونَ {156} أُولَـئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِّن رَّبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ وَأُولَـئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ {157}" (البقرة:155-157)

{Dajudaju, A o dan yin wo pelu nkankan ninu iberu, ebi, adinku ninu awon owo, emi ati awon eso, fun awon onisuuru ni iro idunnu, awon ti adanwo ba ba won ti won o sope: dajudaju, odo Olohun ni ati wa odo Re naa ni a o pada si, awon iye ni awon ike ati aanu yio maa ba lati odo Oluwa won, awon iye ni olumona}. (Suuratu Al -Baqorah: 155-157).

13 - O je titobi ati agbega fun eru: Eni ti o ba je eru ti o se esin re ni mimo fun Olohun, Olohun yio maa be pelu re, eni ti Olohun ba n be pelu re koni yepere, won o si ni bori re. Olohun ti ola Re ga sope:

 " إِنَّ اللّهَ مَعَ الَّذِينَ اتَّقَواْ وَّالَّذِينَ هُم مُّحْسِنُونَ " (النحل:128)

{Dajudaju Olohun nbe pelu awon oluberu (Re) ati awon alusedaada}. (Suuratu An-nahl:128).

 Bawo ni ko se ni ri bayen? Oluni ikapa agbaye, Oluse eda re, Olu-dari re nmoju too pelu iso re, ni ijeri si oro Re ti o sope:

 " وَمَن يَتَوَلَّ اللّهَ وَرَسُولَهُ وَالَّذِينَ آمَنُواْ فَإِنَّ حِزْبَ اللّهِ هُمُ الْغَالِبُونَ " (المائدة:56)

{Eni ti o ba mu Olohun ni aayo ati ojise Re ati awon ti won gbagbo, dajudaju awon ijo Olohun ni olubori}. (Suuratu Al-maaidah:56).

14 - O je iso kuro lodo esu ati awon royiroyi re: eni ti o ba jewo ije eru fun Olohun niti paapa yio soo ni iwaju re, eyin, otun re, osi re, oke re ati isale re. Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّ عِبَادِي لَيْسَ لَكَ عَلَيْهِمْ سُلْطَانٌ إِلاَّ مَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْغَاوِينَ" (الحجر:42)

{Dajudaju, awon arusin mi, ijegaba kan ko si fun o lori won ayafi awon ti won ba tele o ninu awon awon eni-anu}. (Suuratu Al-Hijr:42).

15 - Ifokanbale lo je fun emi: Oun ni itusile fun emi omo eniyan kuro nibi igbonmo iberu ati awon orisirisi iran re, yala iberu lori ohun ti o ti koja tabi iberu lori ohun ti o nsele lowo tabi iburu lori ohun ti nbo wa sele. Eleyi yio sele pelu ifura mo pe gbogbo oro pata nbe lowo Eni ti o se aanu ni oranyan lori ara Re. Bawo ni emi ko se ni bale ti okan ko si ni ni isinmi? Ti o si ngbo oro Olohun ti ola Re ga to sope:

 " وَمَن يَتَّقِ اللَّهَ يَجْعَل لَّهُ مَخْرَجاً {2} وَيَرْزُقْهُ مِنْ حَيْثُ لَا يَحْتَسِبُ وَمَن يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَهُوَ حَسْبُهُ إِنَّ اللَّهَ بَالِغُ أَمْرِهِ قَدْ جَعَلَ اللَّهُ لِكُلِّ شَيْءٍ قَدْراً {3}" (الطلاق:2-3)

{Eni ti o ba beru Olohun Yio se ona abayo fun un 8 Yio si se arisiki fun lona ti ko rokan, eni ti o ba gbokanle Olohun Yio too, dajudaju Olohun Yio mu oro Re se, Olohun ti se ondiwon (kadara) fun gbogbo nkan}. (Suuratu At-talaaq:2-3).

 Gbogbo awon iran iberu omo eniyan yio lo, yio si le lati ara ije eru fun Olohun, nitoripe yio maa fun emi ni onje iyonu ti yio yoo nibi ebi re, ti yio si fun ni amuyo nibi ongbe re.

Ti iberu ba je:

- Iberu nkan ti a o mo: Pelu ije eru fun Olohun kosi iberu fun ohun ti a o mo, kosi si ipaya fun ohun ti nbo, bawo ni eni ti gbo oro Olohun yi se fe beru?

" وَعَدَ اللّهُ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ وَرِضْوَانٌ مِّنَ اللّهِ أَكْبَرُ ذَلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ" (التوبة: 72)

{Olohun se adehun awon ogba idera kan ti akeremodo nsan ni abe re fun awon mumini lokunrin ati lobinrin, won o se gbere ninu re, ati awon ibugbe kan ti won dara ninu awon ogba idera ti won je ibugbe, iyonu lati odo Olohun ni o tobi julo, iye ni erenje ti o tobi}. (Suuratu At-taobah:72).

- Iberu aisan: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

 "مَا أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي أَنفُسِكُمْ إِلَّا فِي كِتَابٍ مِّن قَبْلِ أَن نَّبْرَأَهَا إِنَّ ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ" (الحديد:22)

 {Adanwo kan ko ni sele ni ile bee ni koni sele si awon emi yin ayafi ki o wa ninu tira kan siwaju ki A to da won, dajudaju, iye je irorun fun Olohun}. (Suuratu Al-Hadeed:22).

 - Iberu iku: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

"وَمَا كَانَ لِنَفْسٍ أَنْ تَمُوتَ إِلاَّ بِإِذْنِ الله كِتَاباً مُّؤَجَّلاً وَمَن يُرِدْ ثَوَابَ الدُّنْيَا نُؤْتِهِ مِنْهَا وَمَن يُرِدْ ثَوَابَ الآخِرَةِ نُؤْتِهِ مِنْهَا وَسَنَجْزِي الشَّاكِرِينَ" (آل عمران: 145)

{Emi kan o le ku ayafi pelu iyonda Olohun, o je akosile ti o ni asiko, eni ti o ba fe esan aye A o fun un ninu re, eni ti o ba fe esa ojo ikeyin A o fun un ninu re, A o san awon oludupe lesan}. (Suuratu Aal-imraan:145).

 - Iberu aini ni omo: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

"لِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ يَهَبُ لِمَنْ يَشَاءُ إِنَاثاً وَيَهَبُ لِمَن يَشَاءُ الذُّكُورَ {49} أَوْ يُزَوِّجُهُمْ ذُكْرَاناً وَإِنَاثاً وَيَجْعَلُ مَن يَشَاءُ عَقِيماً إِنَّهُ عَلِيمٌ قَدِيرٌ {50}" (الشورى: 49-50)

{Ti Olohun ni ikapa awon sanmo ati ile, yio maa se eda ohun ti o ba wu U, O maa fi aabo tore fun eni ti o ba wu U, O si maa nfi ako tore fun eni ti o bawu U. * Tabi ki O fun won ni tako- tabo, A si se eni ti o ba wu U ni agan, dajudaju Oun ni Olumo, Olukapa}. (Suuratu Ash-shuura:49-50).

 - Iberu aisan inu emi: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

 " الَّذِينَ آمَنُواْ وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُم بِذِكْرِ اللّهِ أَلاَ بِذِكْرِ اللّهِ تَطْمَئِنُّ الْقُلُوبُ" (الرعد:28)

{Awon ti won gbagbo ti okan won si nbale pelu iranti Olohun, e gbo o! pelu iranti Olohun ni awon okan fi n bale}. (Suuratu Ar-ra'd:28).

 - Iberu awon alabosi: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

"الَّذِينَ قَالَ لَهُمُ النَّاسُ إِنَّ النَّاسَ قَدْ جَمَعُواْ لَكُمْ فَاخْشَوْهُمْ فَزَادَهُمْ إِيمَاناً وَقَالُواْ حَسْبُنَا اللّهُ وَنِعْمَ الْوَكِيلُ {173} فَانقَلَبُواْ بِنِعْمَةٍ مِّنَ اللّهِ وَفَضْلٍ لَّمْ يَمْسَسْهُمْ سُوءٌ وَاتَّبَعُواْ رِضْوَانَ اللّهِ وَاللّهُ ذُو فَضْلٍ عَظِيمٍ {174} إِنَّمَا ذَلِكُمُ الشَّيْطَانُ يُخَوِّفُ أَوْلِيَاءهُ فَلاَ تَخَافُوهُمْ وَخَافُونِ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ {175}" (آل عمران: 173-175)

{Awon ti awon eniyan so fun won pe dajudaju awon ti parojo de yin, nitorina e beru won, eleyi si mu igbagbo won lekun won si, won si sope: Olohun ti to wa, O si dara ni Olufeyinti. * Won si pada pelu idera ati ola Olohun, inira kan ko kan won, won si tele iyonu Olohun, Olohun je Olola nla. * Dajudaju esu nfi awon aayo re deru ba yin, e mo beru won, e beru Mi ti e ba je onigbagbo ododo}. (Suuratu Aal-imraan:173-175).

 - Iberu osi ati ebi: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

"وَكَأَيِّن مِن دَابَّةٍ لَا تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ" (العنكبوت:60)

{Melomelo awon eranko ti won o le gbe arisiki won ti Olohun nse ije-imu fun ati eyin naa, Oun ni Olugboro, Olumo}. (Suuratu Al-ankabuut:60).

 - Iberu lori arisiki: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

"وَمَا مِن دَآبَّةٍ فِي الأَرْضِ إِلاَّ عَلَى اللّهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ" (هود:6)

{Ko si eranko kan ni ile ayafi ki arisiki re maa wa baa lati odo Olohun, O si mo ibusun re ati ibupadasi re, gbogbo re pata nbe ninu tira ti o han}. (Suuratu Hud:6).

- Iberu aini ri aforijin ese: Pelu ije eru fun Olohun ni igbonmo ifokanbale yio maa sele, bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

" قُلْ يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ أَسْرَفُوا عَلَى أَنفُسِهِمْ لَا تَقْنَطُوا مِن رَّحْمَةِ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ جَمِيعاً إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ" (الزمر:53)

{Sope: mope eyin ti e se aseju ese fun awon emi yin, e mo so ireti nu nibi aanu Olohun, dajudaju, Olohun maa nse aforijin gbogbo awon ese, dajudaju, Oun ni Alaforijin, Onike}. (Suuratu Az-zumar:53).

 - Iberu awon eniyan: Pelu ije eru fun Olohun bawo ni eni ti ngbo oro Olohun yi yio se maa beru?

"وَإِنْ يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ وَإِنْ يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلا رَادَّ لِفَضْلِهِ يُصِيبُ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ" (يونس:107)

{Ti Olohun ba gba e mu pelu inira kan kosi olusipaya re ayafi Oun naa, ti O ba si gbero daada kan ro e kosi oludapada fun ola Re, Yio maa se fun eni ti o ba wu U ninu awon eru Re, Oun ni Alaforijin, Onike}. (Suuratu yuunus:107).

 

 

Ipada si ipile:

Ninu ohun ti awon eniyan panupo le lori ti o si rinle ni pe dajudaju gbogbo nkan ni o ni ipile, gbogbo nkan tuntun ni o si ni ibere, ipile awon eniyan eyokan ni ti o si seri pada si odo Adam (Alafia Olohun ko maa ba). O je baba gbogbo won pata, lati ibi eegun eyin re ni awon eniyan ti bere, won wa po si, won si fonka, Olohun ti ola Re ga so nipa paapa yi pe:

" يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُواْ رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالاً كَثِيراً وَنِسَاء وَاتَّقُواْ اللّهَ الَّذِي تَسَاءلُونَ بِهِ وَالأَرْحَامَ إِنَّ اللّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيباً" (النساء: 1)

{Mope eyin eniyan! E beru Oluwa yin ti O se eda yin lati ibi emi kan soso, O si da iyawo re lati ara re, O si fon awon okunrin ati obinrin ti won po ka lati ara awon mejeeji, e beru Olohun ti e fi nbe ara yin ati molebi, dajudaju, Olohun je Oluso lori yin}. (Suuratu An-nisaai:1).

Oye so pe: nigba ti ipile ba je eyookan, ninu adamo nipe igbagbo akoko naa yio je ayookan, oun naa ni imu Olohun ni okan ati ije eru fun Olohun nikan, ati aini mu orogun pelu Re. Baba awon eniyan ni Adam (alaafia Olohun ki o maa ba) o nbe lori adiokan ti o mo kanga ati ije eru fun Olohun, Olohun ti ola Re ga sope:

"وَمَا كَانَ النَّاسُ إِلاَّ أُمَّةً وَاحِدَةً فَاخْتَلَفُواْ وَلَوْلاَ كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ فِيمَا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ" (يونس:19)

{Awon eniyan o je nkankan ayafi ijo kan soso, leyin naa won yapa si ara won, ti ko ba je oro kan ti o ti gbawaju lati odo Oluwa re ni won o ba dajo larin won nipa ohun ti won nse iyapa si}. (Suuratu yuunus:19).

 Iyapa yi seyo lati ara iyapa irori, isemi ati ede gegebi Olohun se so pe:

" وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِّلْعَالِمِينَ" (الروم:22)

{Ninu awon aami Re ni sise eda sanmo ati ile, ati yiyato awon ede won ati awo won, dajudaju, aami nbe nibi iye fun gbogbo agbaye}. (Suuratu Ar-ruum:22).

 Ninu adamo ni ki iyipada adiokan ati esin je yo ni be, eleyi je ohun ti a nri nibi yiyato awon esin, adiokan ati ohun ti won njosin fun ni ori ile, o wa je tulaasi fun gbogbo awon eniyan pe ki won seri pada si ipile ijosin won, ati esin won ti o ni alaafia, eyi ti won nbe lori re siwaju ki esu to seri won kuro nibe, oun naa ni imu Olohun lokan soso, ati ijuwo-juse sile fun UN, ati igbafa fun titele Re, ati imowo-mose kuro nibi ebo, ti won o maa lo gbogbo ohun ti o pa won lase re ni bi gbogbo ise isemi won lai si ayokuro, ti won ba fe orire, iyi, aponle ati isemi rere, ti won o ba se bee won o to kikoro isemi wo ni aye ati ni ojo ikeyin. Ododo ni Olohun ti o tobi so:

" كِتَابٌ أَنزَلْنَاهُ إِلَيْكَ لِتُخْرِجَ النَّاسَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ بِإِذْنِ رَبِّهِمْ إِلَى صِرَاطِ الْعَزِيزِ الْحَمِيدِ" (إبراهيم:1)

{Tira kan ti A so kale fun o ki o le mu awon eniyan jade kuro ni inu okunkun losi inu imole pelu iyonda Oluwa won, losi onan Oba nla, Oba eyin}. (Suuratu Ibroheem:1).

 

 

Ipepe:

Ipepe nbe ni ibiyi fun awon ti won kii se musulumi, ti won je olaju onilaakaye pe ki won ka itumo awon oro Al-Qur'an ti o je iwe ofin esin islam, won o ri atunse nibe fun gbogbo wahala won ati awon wahala gbogbo agbaye, eyi ti o ni se pelu oselu, oro-aje, awujo ati iwa, sugbon igbamu re ati kiko re nwa bukata si ijina si ife inu won ati sise eleyameya won nipa esin, nitoripe o je ofin ti won gbe kale fun gbogbo awon eniyan titi ti opin aye o fi de, ki se ti awon larubawa nikan gege bi awon ti won ntele iroyin ti nsoni nu se nso, awon idajo re ati awon ofin re kaari gbogbo agbegbe isemi, o si wulo fun gbogbo aye ati gbogbo asiko.

Bakannan won yio ri ninu re awon esi ti o je iwosan ti o kun keke fun gbogbo awon ibeere won ti o nwa si inu irori opolopo ninu awon ti won ki se musulumi nipa isemi, iku ati ohun ti n be ni eyin re, (a se tan lati pese eeda kan fun o ti o ba wu e). Pelu bi o se je pe oun ni igbeyin iranse o je tira kan ti nbowo awon esin miran, yala esin awon yaudi ni tabi esin awon kiristani, o si nko lati maa bu adiokan awon elomiran ninu awon elesin ati awon ijo miran, Olohun ti ola Re ga sope:

"وَلاَ تَسُبُّواْ الَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ فَيَسُبُّواْ اللّهَ عَدْواً بِغَيْرِ عِلْمٍ كَذَلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمْ ثُمَّ إِلَى رَبِّهِم مَّرْجِعُهُمْ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُواْ يَعْمَلُونَ" (الأنعام:108)

{E mo bu awon ohun ti won njosin fun yato si Olohun ki awon naa mo fi maa bu Olohun(Allahu) ni ti ikoja aala lai mo, bayi ni A se loso fun gbogbo awon ijo awon ise won, leyin naa odo Oluwa won ni ibupadasi won, Yio si fun won ni iro ohun ti won se ni ise}. (Suuratu Al-An'aam:108).

 Pelu ironu si Al-Qur'an yi won o ri pe o se pelepele ninu iforojomitoro re, o je onfa fun awon okan ni bi alaye re, iwosan fun awon laakaye nibi awon idajo ati ofin re, ododo ni Olohun so nigba ti O sope:

"أَفَلاَ يَتَدَبَّرُونَ الْقُرْآنَ وَلَوْ كَانَ مِنْ عِندِ غَيْرِ اللّهِ لَوَجَدُواْ فِيهِ اخْتِلاَفاً كَثِيراً" (النساء:82)

{Nje won o ni ronu si al quran ni? Ti o ba jape odo eni ti o yato si Olohun ni o ti wa ni won o ba ri iyapa ti o po ninu re}. (Suuratu An-nisaai:82).

Oro ni se pelu ikangun, mo Eni ti O je Olohun re ni ododo, Eyi ti wa fi okan bale si odo Re, ti wa si ni isinmi pelu ijosin Fun Un, wa si mo gbadun pelu pipe Re jeeje, ki o le se orire pelu ifokanbale ati isinmi ni aye, ati sise gbere ni awon ogba idera ni ojo ikeyin, gbe ara re jina si aimokan ati ikose afoju eyi ti o maa ndi awon okan pa, ti koni je ki o gba ododo tabi teti si i, ki o le de ibi paapa mimo Olohun Oba mimo ti ola Re ga. Anfaani ni eleyi je, o pondandan ki o loo ni opin igba ti ilekun iseri tituba ati iseripada si odo Olohun si wa ni sisi, siwaju ki ojo iku to de wa ba o ni ojiji, abamo koni wulo mo ni igba naa, kosi beru abosi tabi iyanje lodo Olohun, koda maa dunnu pelu ohun ti yio dun mo e, nigba ti o je pe yio se aforijin gbogbo ohun ti o ti siwaju ninu awon ese re ati awon asise re, anfaani naa koni bo mo o lowo, Olohun ti ola re ga nsope:

"قُل لِلَّذِينَ كَفَرُواْ إِن يَنتَهُواْ يُغَفَرْ لَهُم مَّا قَدْ سَلَفَ وَإِنْ يَعُودُواْ فَقَدْ مَضَتْ سُنَّةُ الأَوَّلِينِ {38}" (الانفال:38)

{So fun awon ti won se aigbagbo pe: ti won ba jawo (ni bi aigbagbo) won o se aforijin ohun ti o ti siwaju (ninu awon ese won), ti won ba si seri (pada sibe) apejuwe awon eni akoko ti gbawaju}. (Suuratu Al-anfaal:38).

Dajudaju emi mo amodaju pe opolopo ninu awon eniyan won o yonu si ohun ti won nbe ninu re, nipa jijosin fun nkan miran yato si Olohun okan soso ti o je Olubori, Eni ti O se eda won ti O si so won di bibe lati ibi aisi, ni adayanri awon ti won njosin fun awon eda bii ti won, bi eranko ati awon ohun adamo ti a nfoju ri. Dajudaju ire o se emo nipa eni ti nwa awon olohun ti yio ma josin fun ti laakaye ti o ni alaafia si tako o, ati eniyan ti o ni olaju ninu awon ti won njosin fun ina, awon esu, awon eku ati bee bee lo, okan won ti foju ki awon oju won to fo kuro nibi ijosin fun Olohun Oluwa ododo. Ododo ni Olohun ti o tobi so:

"فَإِنَّهَا لَا تَعْمَى الْأَبْصَارُ وَلَكِن تَعْمَى الْقُلُوبُ الَّتِي فِي الصُّدُورِ" (الحج: 46)

 {Dajudaju, awon oji kii fo, sugbon, awon okan ti n be ni igbaya maa nfo}. (Suuratu Al -Hajj:46).

 Eni ti o ba fe ododo Olohun yio fi se konge, ti Olohun ba mo ododo re lori eleyi, Olohun ti ola Re ga sope:

"وَمَن يُؤْمِن بِاللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ" (التغابن: 11)

{Eni ti ba gba Olohun gbo yio fi onan mo okan re, Olohun ni Olumo nipa gbogbo nkan}. (Suuratu At-taghoobun:11).

Ma se maa be ninu awon onigberaga si ododo, ati awon ti won nje gaba lori awon eniyan, ti ododo yio fi wa pare ninu okan re, ti ebibo yio si bo oju re, o wa ni ri nkankan ayafi ohun ti o ba ba ife inu re mu, ti yio wa je okunfa iparun re. Olohun ti ola Re ga sope:

"سَأَصْرِفُ عَنْ آيَاتِيَ الَّذِينَ يَتَكَبَّرُونَ فِي الأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَإِن يَرَوْاْ كُلَّ آيَةٍ لاَّ يُؤْمِنُواْ بِهَا وَإِن يَرَوْاْ سَبِيلَ الرُّشْدِ لاَ يَتَّخِذُوهُ سَبِيلاً وَإِن يَرَوْاْ سَبِيلَ الْغَيِّ يَتَّخِذُوهُ سَبِيلاً ذَلِكَ بِأَنَّهُمْ كَذَّبُواْ بِآيَاتِنَا وَكَانُواْ عَنْهَا غَافِلِينَ" (الأعراف:146)

{Maa gbe awon ti won nse igberaga ni ori ile lai ni eto jina si awon aami Mi, ti won ba ri gbogbo aami won o ni gbaagbo, ti won ba ri onan imonan, won ni gbaamu ni onan, ti won ba ri onan anu won o gbaamu ni ona nitoripe won npe awon aami Wa ni iro, won si ya afonu-fora nipa re}. (Suuratu Al-A'roof:146).

Seri si odo Olujosin fun re ni ododo, waa ri i ni alaanu fun o ju iya re ti o loyun re lo, ti o bi o, ti o fun o ni oyan, ti o si toju re. Olohun ti ola Re ga sope:

"هُوَ الَّذِي يُصَلِّي عَلَيْكُمْ وَمَلَائِكَتُهُ لِيُخْرِجَكُم مِّنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ وَكَانَ بِالْمُؤْمِنِينَ رَحِيماً" (الأحزاب: 43)

{Oun ni nse ike fun yin ati awon malaika Re ki O le mu yin kuro ninu okunkun wasi inu imole, O je Alaanu fun awon onigbagbo ododo}. (Suuratu Al-Ahzaab:43).

 O maa ndunnu pelu siseri eru re si odo Re, ati ironupiwada re losi ibi ijosin fun Un, gegebi ojise Olohun (ki ike ati ola Re maa ba) se so iroyin nipa eleyi nigba ti o sope: "dajudaju Olohun maa npo ni idunnu pelu ituba eru Re ti o tuba ju eni kan ti o so nkan gun re nu lo ni ile kan ti o je asale ti o le ko iparun bani, ti onje re ati omi re nbe leyin (nkangun naa), o wa waa kosi ri i, o wa sun si abe igi kan, nigba ti yio ji ni o ba ri nkangun re ti onje re ati omi re nbe leyin re, Olohun po ni idunnu pelu ituba eru Re ju eni yi pelu nkan re lo." (Muslim).

 

 

Ipari:

 Ire ololufe mi ti o je oluka iwe yi, dajudaju mo je olukilo ati alaanu fun o, dajudaju moje ololufe fun o, dajudaju ojukokoro mi lati le se awon eniyan ni anfaani ni o mimu ko iwe yi, "eniyan ti o je olorire julo ni eni ti anfaani re si awon eniyan po ju." (Saheeh Al-Jamii') gege bi esin wa se ko wa, ti o si to wa sona losi ibe, aanu won ni o ti mi losi ibe, "awon oluke eniyan Oba Ajoke aye yio ke awon naa." (Musnad Ahmad), gege bi Oluwa wa Oba mimo ti ola Re ga se pawa lase, inife daada si elomiran oun ni o hu eleyi sile, gege bi ojise wa Muhammad (ki Olohun se ike ati ola fun) se so iro nipa re, "nife si awon eniyan iru ohun ti o ni ife re fun ara re" (Sunan At-trmidhi), gbogbo awon itosona ti o wa lati odo Olohun yi lapapo ni o mu mi lo opin igbiyanju ti mo ni lati fi ododo han eyi ti o le pamo si yin, nitori iroyin agbelero ti o yato si ooto, tabi ti o maa nyi paapa nkan pada, eyi ti o maa ngbe awo aguntan wo okan ikoko, ti yio so ododo di iro, iro di ododo, ibaje di ooto, ooto di ibaje, olorire ti Olohun fi se konge ni eni ti o le se adayanri awon nkan wonyi, ti yio mu ooto ninu re ti yio si ju ibaje inu re nu. Awon itosona ti o wa lati odo Olohun won npepe losi ibi sise iwadi nipa gbogbo nkan, ati aini mu nkan se ayafi leyin sise ofintoto ati alaye. Olohun ti ola Re ga sope:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِن جَاءكُمْ فَاسِقٌ بِنَبَأٍ فَتَبَيَّنُوا أَن تُصِيبُوا قَوْماً بِجَهَالَةٍ فَتُصْبِحُوا عَلَى مَا فَعَلْتُمْ نَادِمِينَ" (الحجرات:6)

{Mope eyin ti e gbagbo! Ti pooki eniyan kan ba mu iroyin kan wa fun yin e se iwadi, ki e mo ba sise nipa awon kan pelu aimo, ti e o fi wa di alabamo lori ohun ti e se}. (Suuratu Al-hujuroot:6).

Ki eni ti njosin fun nkan miran yato si Olohun ma se gba itanje pelu ohun ti n be ninu re ninu alaafia, opo owo, awon omo, ti ile aye ba se dede iye yanmuyanmu ni odo Olohun ni ki ba ti fun ni omi gee kan mu eni ti o se aigbagbo si I, ti o si njosin fun nkan miran yato Si I. Olohun ti ola Re ga sope:

"وَلاَ يَحْسَبَنَّ الَّذِينَ كَفَرُواْ أَنَّمَا نُمْلِي لَهُمْ خَيْرٌ لِّأَنفُسِهِمْ إِنَّمَا نُمْلِي لَهُمْ لِيَزْدَادُواْ إِثْماً وَلَهْمُ عَذَابٌ مُّهِينٌ" (آل عمران:178)

{Ki awon ti won se aigbagbo ma se rope lilowon lara ti A lo won lara ni oore fun won, dajudaju, A lowon lara ki won le lekun ninu ese, iya iyepere nbe fun won}. (Suuratu Aal imraan:178).

Pipo oore ninu awon idekun aye kii se apere ife Olohun fun o ati iyonu Re si ise re, Olohun maa nfun ni aye eni ti o nife ati eni ti ko nife, sugbon itele Re ati ijosin Re kii fun enikankan ayafi eni ti o nife, ona wa ni sisi fun o lati wa ninu eni ti Olohun n nife, ti Yio si yonu si ise re, eleyi pelu ije eru fun Un ni tooto, O tun sope:

"وَلَوْلَا أَن يَكُونَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً لَجَعَلْنَا لِمَن يَكْفُرُ بِالرَّحْمَنِ لِبُيُوتِهِمْ سُقُفاً مِّن فَضَّةٍ وَمَعَارِجَ عَلَيْهَا يَظْهَرُونَ {33} وَلِبُيُوتِهِمْ أَبْوَاباً وَسُرُراً عَلَيْهَا يَتَّكِؤُونَ {34} وَزُخْرُفاً وَإِن كُلُّ ذَلِكَ لَمَّا مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَالْآخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلْمُتَّقِينَ {35}" (الزخرف:33-35)

{Ti ki ba se ki awon eniyan mo ba je ijo kan naa ni A o ba se awon pepe lati ibi fadaka fun awon ile awon ti won se aigbagbo si Oba Ajoke aye, ati awon ategun kan ti won mo gunke lati ibe. * (A o ba se) awon oju ona kan fun awon ile won ati awon timutimu kan ti won o mo rogboku lori re. * Ati awon nkan igbadu, gbogbo re pata ko je nkankan ayafi igbadun isemi aye, ojo ikeyin si nbe fun awon oluberu Olohun}. (Suuratu Az-zukhruf:33-35).

Dajudaju ohun ti eniyan kojo, ti o fi sile ko le se ni anfaani, ninu owo ati omo ti o ba ku lori ijosin fun nkan miran yato si Olohun, koda yio je ofo fun ni ojo igbende, gege bi Olohun se so iroyin nipa eleyi ninu oro Re pe:

"وَمَا أَمْوَالُكُمْ وَلَا أَوْلَادُكُم بِالَّتِي تُقَرِّبُكُمْ عِندَنَا زُلْفَى إِلَّا مَنْ آمَنَ وَعَمِلَ صَالِحاً فَأُوْلَئِكَ لَهُمْ جَزَاء الضِّعْفِ بِمَا عَمِلُوا وَهُمْ فِي الْغُرُفَاتِ آمِنُونَ" (سبأ:37)

{Awon owo yin ati awon omo yin won o je nkan ti yio sun yin mo Wa ni ipo, ayafi eni ti o ba gbagbo ti o si se ise rere, awon ye ni won ni adipele esan nitori ohun ti won se ni ise, won o si je olufokanbale ninu awon yara}. (Suuratu Sabai:37).

Yio duro ni ojo iseri ati isiro ni oun nikan lai si gbogbo nkan ti o ni laye, lai wo bata, ni ihoho, lai da abe, gegebi won se se eda re ni akoko. Olohun ti ola Re ga sope:

"وَلَقَدْ جِئْتُمُونَا فُرَادَى كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَتَرَكْتُم مَّا خَوَّلْنَاكُمْ وَرَاء ظُهُورِكُمْ وَمَا نَرَى مَعَكُمْ شُفَعَاءكُمُ الَّذِينَ زَعَمْتُمْ أَنَّهُمْ فِيكُمْ شُرَكَاء لَقَد تَّقَطَّعَ بَيْنَكُمْ وَضَلَّ عَنكُم مَّا كُنتُمْ تَزْعُمُونَ" (الأنعام: 94)

{Dajudaju, e de wa ba Wa leyo kookan gege bi A se se eda yin lakoko, e si fi gbogbo ohun ti A fun yin sile ni eyin yin, A o ri pelu yin awon olusipe ti e nsope wo nbe pelu yin ti won je orogun, onpinya ti de si aarin yin, o si ti bo fun yin ohun ti e nso}. (Suuratu Al-An'aam:94).

Ohun ti o tobi ju ti o ye ki o se iwadi nipa re ni esin re ati adiokan re, gege bi o se je pe o nwa ifinilokan bale lori owo ti o nna lori owo sise ti o je ti re nikan, nitori ki o le mo pe (ere nbe lori re), dandan ni ki o se iwadi nipa esin re ati adiokan re, o gbodo mo amodaju nipa didara ohun ti o nse ninu esin ati adiokan, ki o to di wipe wa se abamo ni asiko ti abamo ko ni wulo, ki ododo le han si o yato si ibaje, o le se mi ni ori ile yi ayafi isemi kan soso, gbiyanju ki o se konge sise sa esin ti o ni alaafia, ojogbon eniyan ni eni ti o je emi re nipa, ti o si sise fun ohun ti n be leyin iku, Olohun ko wa ni odo re ayafi nkan die, oun naa ni ijosin fun Un, ati lilo ofin Re, O roro tayo re, O si se adehun nkan ti o po fun o, isemi gbere ni abe iboji idekun ti ko ni tan. Omugo ni eni ti o ta ohun ti yio seku ti o fi ra ohun ti yio tan. Ire eniyan naa ni eni ti yio se anfaani ni ibere ati ni apari, iyapa awon oluyapa ko ko inira ba Olohun, bee ni itele awon olutele ko se E ni anfaani, sugbon igbidanwo lo je, nitori ki olutele le foju han yato si oluyapa. Olohun ti ola Re ga sope:

"وَلَقَدْ فَتَنَّا الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَلَيَعْلَمَنَّ اللَّهُ الَّذِينَ صَدَقُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْكَاذِبِينَ" (العنكبوت:3 )

{Dajudaju, A ti gbidanwo awon ti won saaju yin, dajudaju Olohun yio mo awon ti won so ododo, dajudaju, Olohun yi o mo awon opuro}. (Suuratu Al-ankabuut:3).

 Ije eru fun Olohun ti to fun o lati ri orire laye ati ni ojo ikeyin, ki i se owo ati ipo, koda iboji ti yio ye ni o je, oo le fi ra awon daada ni ojo igbende, oo si le fi moribo ni bi awon aburu. Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُواْ لَوْ أَنَّ لَهُم مَّا فِي الأَرْضِ جَمِيعاً وَمِثْلَهُ مَعَهُ لِيَفْتَدُواْ بِهِ مِنْ عَذَابِ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَا تُقُبِّلَ مِنْهُمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ" (المائدة: 36)

{Dajudaju, awon ti won se aigbagbo, ti o ba je pe gbogbo ohun ti nbe ni ile je ti won ati eru re pelu re, ki won le fi ropo iya ojo igbende, won o nig baa lowo won, iya eleta-elero sin be fun won}. (Suuratu Al-maaidah:36).

 Mo be Olohun ki O fun iriran re ni imole, ki O si fi okan re mona, ki O fi o mo ona ododo, ki Olohun se ike ati ola fun anobi wa Muhammad ati awon ara ile re ati awon saabe re.

Ti o ba ri be! Bawo ni agbaye yi ati ohun ti nbe ninu re: sanmo, ile, oorun, osupa, oru, osan, awon irawo, nje awon nkan wonyi ko toka re si bibe Eni ti o ni ki awon nkan naa maa be ti O se eda won? Adeda ni yi, kini O fe lodo eda yi, atipe nitori kini O si fi se eda re?

 

www.islamland.com