GBOGBO ADADASILE NINU ESIN ANU NI

GBOGBO ADADASILE NINU ESIN ANU NI

GBOGBO ADADASILE NINU ESIN ANU NI

كل بدعةٍ في الدين ضلالة بلغة اليوروبا

 

 

‘Abd Ar-Rahmân bin ‘Abd Al-Karîm Ash-Sheha

د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 

 

Itumo ni ede Yoruba

EUROPEAN ISLAMIC RESEARCH CENTER (EIRC)

المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية

& Abd Ar-Razzaq Isa

Atunto

Ridwanu Allah Murtadho

 

WWW.ISLAMLAND.COM

 

 

 

GBOGBO ADADASILE NINU ESIN ANU NI

Ni oruko Allaahu, Ajoke Aye Asake Orun

           

Gbogbo ope je ti Olohun, a o maa yin – in, a o maa fi se alatileyin wa, a o maa wa aforijin sodo re, a o maa fi Allaahu wa iso nibi gbogbo aburu emi wa ati awon asise owo wa, eni ti Olohun ba fi ona mo, oun ni koni sonu, eni ti Allaahu ba sonu, oun ni ko ni ri olufinimonaa. Emi yoo maa mu ijeri wa wi pe ko si Olohun miran ayafi Olohun nikan ti ko lorogun. Emi yoo maa mu ijeri wa wi pe Anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun ma ba) erusin Re ni ojise Re si ni pelu, ike Olohun ati Ola Re lopolopo ko maa ba a titi di ojo esan, leyinaa.

 

Oro Isaaju

           

Dajudaju oro esin je ohun ti gbigba ati mimulo o re pan dandan, bakannaa a kogbodo gunri kuro nibi titele ase Olohun nibamusi oro Olohun ti ola Re ga so pe:

" وَمَا آتَاكُمُ الرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَاكُمْ عَنْهُ فَانتَهُوا وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ" {الحشر/7}

 “Ohunkohun ti ojise ba fun yin, e gba a, ohunkohun ti o basi ko fun yin e jawo ninu re, Ki e si beru Olohun, Dajudaju Olohun lekoko nibi ifi iya je ni”. (al-hashr: 7)

Gegebi titele ilanan ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) se je oranyan ati aimomo se igbiyanju nibi ti ko fi aaye igbiyanju sise sile si, nibamusi oro Olohun ti Ola Re ga julo to sope:

"قُلْ إِن كُنتُمْ تُحِبُّونَ اللّهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللّهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَاللّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ" {آل عمران/31}

“Sope: dajudaju ti eyin ba n nife Olohun, e tele mi, Olohun yoo nifee yin, yoo si fi ori awon ese yin jin yin, Olohun ni Alaforijin, Alaanu” (Aali – Imroon: 31).

Gegebi a ko se gbodo fi ohun ti kosi ninu esin si inu re, nitori wipe o je ohun ti o le sokunfa adinku, ti o si le si awon ona iyapa – enu orisirisi sile, eleyi ti yoo gbe eru jinna si Ojuona ti o ni alaafia ti Olohun gbe kale, ti yoo si fa iya ati ibawi Olohun fun. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

“Enikeni ti o ba da adadasile ninu oro wa yii, (ninu esin wa yii), ohun ti kosi ninu re, a o da pada fun u” (bukhori ati muslim)

Opolopo awon ti won pe apemora esin mo ara won ni won n se awon ise kan ti o ni se pelu esin, ti ohun ti won n se yii si yato si ohun ti Islam mu wa lati kowa, tabi ki a so wipe won n se awon adadasile eleyi ti ko ni ipile kankan ninu esin, bi kose pe won kan n tele ife inu won ati ase aburu eleyi ti emi won pa won, bee si ni pelu awon ise won yi won yoo je eni eebu. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"أَرَأَيْتَ مَنِ اتَّخَذَ إِلَهَهُ هَوَاهُ أَفَأَنتَ تَكُونُ عَلَيْهِ وَكِيلا" {الفرقان/43}

“Nje ire ko wa ri eniti o so ife – inu re di Olohun re! Nje iwo wa le je oluso fun u bi”? (Al – Furqoon : 43)

Gbogbo awon iyapa ati awon adadasile ninu esin wonyii, ti o ba je wi pe ipalara re mo lori eniti o se adasile re nikan ni, ti ko si tatapo de odo elomiran, oro iba sepere, tohun ti bi o se je wipe a o ni yonda fun won ki won se e, – sugbon awon iyapa yii ati adadasile wonyi ni ilapa nla lori awon Musulumi yoku, nibi ki a ri ninu won eni ti yoo ka awon adadasile yii si ohun ti o dara, beesini awon adadasi yii je ponpo fun ida esin wo, gegebi o se je ilapa aburu lodo awon ti kii se Musulumi, toripe nigba ti won ba ri awon ihuwasi ati isesi awon apakan ti won n fi ara won ti si esin nibi awon alamori ijosin, paapa julo nibi awon nkan to sepe lakai ti oni alaafia ma nko, ti o si tun tako paapa ilana –At-taoheed-(ise Olohun ni okansoso) ati adamo rere, ti yoo si ma le awon eniyan jina si Islam, ti won yoo wa ka si iru awon ilana ofin miran eleyi ti won mon lori awon ilana agbelero ti kosi ba opolo mu.

Ona meta ni awon Oni-ihuwa si yi ati awon adadasile wonyi pin si. Awon ona naa niyii:

1.         Ipin Alakooko: Ninu ko je wi pe awon ti aimokan nipa esin sokunfa adadasile won ti won n se, beesi ni Islam o foju fo eleyi, tori wipe ibeere ni oogun aimokan, nipa bayi a ki se ise nibamu si ife-inu ati ohun ti emi ba fe. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"فَاسْأَلُواْ أَهْلَ الذِّكْرِ إِن كُنتُمْ لاَ تَعْلَمُونَ" {الأنبياء/7}

“Nitori naa, e bi awon onimomo leere ti e yin ko ba mo”. (al-anbiya:7)

Tabi ki o je pe pelu iteleni ti afoju, ati titele awon to siwaju eni. Irufe ise awon wonyi je buburu. Olohun ti Ola Re ga julo ti so nipa irufe awon wonyii pe:

"وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّبِعُوا مَا أَنزَلَ اللَّهُ قَالُوا بَلْ نَتَّبِعُ مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءنَا أَوَلَوْ كَانَ الشَّيْطَانُ يَدْعُوهُمْ إِلَى عَذَابِ السَّعِيرِ" {لقمان/21}

 “Nigba ti won ba si so fun won pe: “E tele ohun ti Olohun sokale “Won a wi pe: “Rara! A maa tele ohun ti a ba lowo baba wa ni” tohun ti bi Esu se n pe won sibi iya ina jonijoni?. (luqman-21)

Irufe awon wonyi je eni ti n be lori anu nibi ijosin won, ti o yapa si eyi ti Olohun se lofin, Ijosin pupo irufe awon wonyi o le se won ni anfaani Kankan. Ijosin kekere ti o wa nibamusi itele Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) loore o si dara pupo fun eni ti o se e ju ijosin pupo ti o wa nibamusi ilana ti o yapa si (Sunnah) Ilana Ijosin Ojise Allaahu (ki ike ati ola Olohun ma ba)

2.         Ipin Elekeeji: Awon iran keji ni awon to se pe ife aye ati akolekan awon nnkan igbadun mu won ma se anfaani pelu aimokan awon eniyan nipa alamori esin won, nibi nini opolopo olutele won, lati le ri awon ohun igbadun ti won nfe, ki won si fi le de awon ipo lawujo, awon wonyi jinna tefe si esin. Nbe ninu won awon ti won n pe Islam mo ara won, beesi ni Islam ti tuwo loro won, irufe awon wonyi ni won wo Islam ni aso ti ki se tie, won wa fi abuku kan Islam pelu adadasile ati agbelero esin ti won sin.

3.         Ipin Elekeeta: Awon iran keta ni awon ti won n sakitiyan pelu orisirisi ategun lati tan adadasile ninu esin kaakiri, nitori a ti le tu ijo Islam ka, won si n na gbogbo owo ati dukia topo repete fun eni ti o ba gba lati da adadasile sinu esin Islam ki won o ba le tan adadasile ka, ti yoo wa se okunfa bi be orisirisi ijo ati egbe ti o yapa si ilana ijosin Olohun, Oba Adeda, ti apakan won yoo wa ma tako apakeji nipase yiyapa si ara won ati pipo ilana ti okookan won ntele, bayi ni ohun ti ota Islam nfe ba di ohun amuse nibi lile awon eniyan jina si esin won, ati adiokan won ti o je eyiti o ni Alafia pelu inawo ran npe ati anan danu kekere.

 Adadasile ati awon agbelero ninu esin je ise Eesu, royiroyi re ati ete re ti o maa n lo lati da esin ru mo awon eniyan lowo.

Omo Abbãs (ki Olohun bani yonu si baba ati omo) sope lori oro Olohun to lo bayi:

"وَقَالُوا لاَ تَذَرُنَّ آلِهَتَكُمْ وَلاَ تَذَرُنَّ وَدًّا وَلاَ سُوَاعًا وَلاَ يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسْرًا" {نوح/23}

“Won si wi pe: “E ma se fi awon orisa yin sile. E ma se fi orisa Wadd, Suwaa’u “Yeguuth, Ye’uuq ati Nasr sile”. (nuhu:23)

Omo Abbãs (ki Olohun bawa yonu si) so pe: Awon oruko orisa inu Ayat yi je awon oruko awon eniyan rere ninu iran Anabi Nuh, sugbon nigba ti won ku, Eesu gbe si okan awon eniyan won pe ki won gbe ere won si okookan aaye ti awon eniire yii maa n joko si, ki won si so awon ere wonyi ni oruko awon eniire naa, awon eniyan won si sebee, awon wonyii, ko sin won titi ti won fi kuro laye. Leyin ti o pe ti igbagbe ba idi ti won fi gbewon lere, won ba pada di eni ti awon eniyan n sin – in.

Alfa wa omo Quayyum (Ki Olohun bawa ke) soro lori nnkan yii lasiko ti n soro lori ipele bi eesu se maa n tan omoniyan je, o so wipe:

“Dajudaju Eesu fe jere siso omo Adam nu latari ipo kan ninu awon ipo meje eleyi ti awon kan ninu ipo wonyi si le ju awon kan lo, Eesu o si ni sokale lati ibi ipo to nira pupo wa si eyi ti konira pupo to t'akoko ayafi ti o ba kagaara a ti ri omoniyan je lere” Awon ipo wonyi nii:

1.         Ipo Aigba Olohun gbo: aigba esin Re gbo, aigba pipade Re gbo, aigba iroyin Allaahu gbo ati aigba iroyin ohun ti Ojise Olohun(ki ike ati ola Olohun ma ba) mu wa gbo, nitori pe ti o ba ti ri ipo eyi je lere, ina ti di wiwo fun iru eni yi latari mimu lota ti Eesu mu iru eni bee lota, Eesu yoo si sinmi, ti o ba wa je wi pe ko yege yoo wa ona atile si lona lo si ipo to kan leyin eyi.

2.         Ipo Adadasile: Ninu ki o ni igbagbo nipa n to tako ododo eyi ti Allaahu firan ojise Re, ti o si titori re so tira kale, tabi latari mi maa se esin pelu ohun ti Allaahu ko yonda funni lati fi sin, bii sinsin aworan, ti awon kan gbe kale eleyi ti o je adadasile ninu esin, ti o si je ohunkan ti Allaahu ko ni gba ikankan gegebi ijosin nibe. Beesi ni ki esu jere pelu siso omoniyan nu latari adadasile gan – an lo nife si ju, idi ni pe atako esin ni adadasile je, bakannaa o si tun je gbigba danu fun ise ti Allaahu titori re gbe ojise dide, eni ti o ba je aladasile kii si tun tete ronupiwada tabi ki o jawo nibe, bikosepe yoo tun maa pe awon miran lo sibe ni. Bakannaa lo tun je ona lati maa so oro nipa Olohun laini imo, eleyi si je atako fun (Sunnah) ilana ijosin ti tolohun. Tori idi eyi awon adadasile kekere kekere maa n tan eniyan je lo si ibi nla ni, titi ti yio fi faa eniyan yo kuro patapata ninu esin gegebi won se maa n yo jero kuro ninu gaari, enikankan ko ni mo awon ona ibaje adadasile yii ayafi awon olurinan, ti eniyan ba wa mu ori bo nibi ipo yi, to bo nibi ajaga eyi pelu imole Sunnah, ti o ri idaabo pelu titele Sunnah daadaa ati pelu titele ilana ijosin awon asiwaju rere bi awon sahabe ati Taabihii (awon to telewon), eesu tun maa wa ona abayo si ipo miiran to tun kan leyin re.

3.         Ipo dida awon ese nlanla : Ti Eesu ba jere latari eleyi, yoo mura si ki o maa koso ba ese yi sii, nigba miran o kan le gbe oro kan gba ori ahon ati eti eniyan lo, to si je pe iru oro bee maa n ko iparun ba omoniyan ni, fun apeere, iru oro bii “Ese dida ko ba mimu Olohun lokan eni je, gegebi o se je pe ise rere ko se ebo naa lanfaani” Ti omoniyan ba tun mori bo kuro nibi iru ipo yi, yoo tun wa ona abayo si ipo miiran to tun tele eleyi.

4.         Ipo Ese kekere kerere: Eesu koni ye koni gbo leni ti yoo maa wa ona lati le se ese sise nirorun fomoniyan pelu ki o ko nigbolohun bii: Ko si ese Kankan fun e lori eyi, nigba ti o ba ti le ri wi pe oun jinna si ese nlanla, Eesu o maa so fun omoniyan pe won o le ko akosile wi pe o da ese fun – un, yoo ran leti wi pe se ko mo wi pe won maa n fi awon ise rere pa ese kekere kekere re fun eniyan ni, nigba ti o ba ti jinna si awon ese nlanla. Koni ye koni gbo titi ti yoo fi je kororun lati maa da ese titi ti yoo fi di baraku fun – un, ti yoo fi le pada maa da awon ese nlanla awon ese tii maa n pani laya, ti eniyan maa kabamo fun didaa re nigbeyin. Ki eniyan si taku sidi ese dida gan – an buru ju ese gangan fun ra re lo.

Ko si ese nla pelu wiwa aforijin, kosi si ese kekere pelu ima taku s'ori ese, Ojise Olohun (ti ike ati ola n be fun) so pe: "Odowo yin, lati sora fun imaa foju kere awon ese, oro naa dabi awon eniyan kan ti won gunle si inun ogbun, ti lagbaja de pelu igi isepe kan, ti tamadun naa de pelu igi isepe miran, titi ti won fi se buredi won jinnan, dajudaju awon ese kere tia f'oju di, ti eni ti n da iru ese bee bati mu nise, yio ko iparun baa ni". (Ahmad).

Ti omoniyan ba mori bo nibi ipo eyi pelu fifi Olohun wa iso ati aabo, ati opolopo ironupiwada ati wiwa aforijin, ti o si n fi daadaa pa asise re re, Eesu yoo tun wa ona lati si lona pelu ti taari re lo sibi ipo ti o tele eleyi.

5.         Ipo mi maa se awon ohun ti kosi ese nibi sise re: titi ti eniyan yoo fi waa sairoju nibi sise opolopo awon ise daada, ati igbaradi fun Ojo Igbende re naa. Leyin naa yoo taari re lo sibi mi maa gbe sunnah ju sile, lati ibe ni yoo ti taari re lo sibi gbigbe awon oranyan ju sile.

 Ti omoniyan ba tun mori bo nibi ipo eleyi pelu mimon iyi itele ase Olohun, bakannaa ti o tun mo iyi ki itele ase Olohun re po, Eesu yoo ba tun wa ona abayo sisi lona si ipo ti o tele eyi.

6.         Ki Eesu taari omoniyan lo sibi mi maa se awon ise ti o tewon: ti o si lola, yoo pa lase re, yio di ohun to dara ju loju araa re, yoo tun se e loso fun – un, yoo je ki o mo ola towa nibe, yoo je komo ere ibe pelu, kofi le kairoju kuro nibi eyi ti o lola ju iyen lo, ti erenje ibe si tobiju, nitori pe nigba ti o kagara lati di lowo erenje ipile, osagbokante lati moje kori esan nan pe perepere, nipa bayi Eesu yoo waa je ko sairoju nibi eyi ti o lola titi yoo fi pa eyi ti o lola ju eyi ti n se lo ti, bakannaaa ti yoo si pa eyi ti o tewon julo pupo ti, nitori omiran ti ohun naa tewon die, ti yoo fi maa se eyi ti Olohun nife si, sugbon ti yoo gbe eyi ti Olohun nife si pupopupo ju sile.

Ninun onan ti eesu ma n gba lati mu awon eniyan se adadale ni siso ohun ti ojise Allaahu ko so, ileri iya ti o le koko siti wa lori eleyi. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

“Iro pipa mo mi koda bii iro ti e maa n pa mo araayin, enikeni ti o ba pa iro mo mi, ki o yaa mu ibujoko re ninu inan" (Bukhori)

Sahabe Pataki kan tii se omo Mashood ki Olohun bani yonu si so bayi pe: “E maa tele ase ni, e ma se ma’a da adadasile, won ti funyi ni ohun ti toyin o. (nibi gbogbo ohun ti e nilo nibi itele ase Olohun)” (Tobaraani)

Abdul Rahman omo Abdul kareem As – Shaiha.

 

 

 

NJE ESIN ISLAM ESIN TO PE NI?

 

Ninu ohun ti a mo nipa esin Islam dajudaju ni wi pe o pe, o si ti pari, oro Allaahu ti o ga julo so pe:

"الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الإِسْلاَمَ دِينًا" {المائدة/3}

(Loni ni mo pa ri esin yin fun yin. Mo si se asepe idere mi fun yin. Mo si yonu si Islaam ni esin fun yi).            (Suurah – Al – Moo’idah : 3)

O si so nipa gbogbo nnkan to so mo aye ati orun omoniyan. Olohun ti ola Re ga julo so pe:

"وَنَزَّلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ تِبْيَانًا لِّكُلِّ شَيْءٍ")سورة الـنحل: 89(

“A so Tira kale fun o (ki o le je) Alaye fun gbogbo nnkan”. (suurah an-nahl 89)

 Ohun ti won ko ba se alaye re pelu akosile inu Al – Qur’aan Alaponle tii se iwe ipile fun ofin Islam, yio je ohun ti won salaye ninu ipile keji fun ofin, eleyi tii se Sunnah Rosuulaahi ti ike ati ola nbe fun. Yala o je ti toro enu, tabi ti ise re, tabi eyi ti ko soro lori i re sugbon ti ko tako o, eleyi ti won mu wa lona ti o ni alaafia. Olohun ti Ola Re ga julo, so pe:

"وَأَنزَلَ اللّهُ عَلَيْكَ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَعَلَّمَكَ مَا لَمْ تَكُنْ تَعْلَمُ وَكَانَ فَضْلُ اللّهِ عَلَيْكَ عَظِيمًا" (سورة النساء/113)

"Allaahu si so Tira ati oye esin (Iyen Sunnah) kale fun o. O tun fi ohun ti iwo ko mo tele mo o, oore ajulo Olohun ti n be lori re je ohun to tobi". (suurah an-nisaai 113).

Bakanna ninu ohun ti a mo nipa esin Islam to daju tun nipe ojise Olohun (Ti ike ati ola n be fun) je ise de ogongo o si pe Amaanah, o si gba awon ijo re ni imoran to ye kooro Allaahu ti Ola Re ga jul so pe:

"وَأَنزَلْنَا إِلَيْكَ الذِّكْرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيْهِمْ وَلَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ" )سورة النـحل : 44(

"Ati pe A so – Qur’an kale fun o nitori ki iwo le se alaye fun awon eniyan ohun ti A sokale fun won ati nitori ki won le ronu jinle". (An – Nah : 44)

Ati pe ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) kori nnkan kan ti o lore fun wa, afi ki o towasonan losi ibi sise re, bakannaa ko si nnkan buburu kan ayafi ki o wa ijore ni isora kuro nibe. Ojise Allaahu (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

“Kosi Anabi kan ninu awon Anabi Olohun to ti gbawaju mi wa saye ayafi ko je pe ohunkan ti yi o je ojuse re ni ki o maa to awon eniyan re sonan lo sibi daradara ti yi o sewon lanfaani, bakannaa kosi kilo fun awon eniyan re lori gbogbo ohunkan to le je aburu fun won…..” (muslim 3/147, 1844)

Enikeni to ba gba nnkan to yato si eleyi gbo, iru eni bee ti se atako si oro Al – Qur’aan ti won so kale fun Muhammad (ki ike ati ola Olohun ma ba)

Dajudaju aladadasile nibi esin Olohun lero wipe esin Allaahu ko pe, o lero wi pe ohun to ye ni ki ohun se adadasile nnkan kun si, tori wipe eni ti o se adadasile sinu esin Olohun fe pe ohun ti odinku ninu esin ni!

Bakannaa o tun je eni ti n kefin wi pe Rosuululahi (ki ike ati ola Olohun ma ba) se ijamba, kosi jise ti won la bo lorun dogongo pelu adadasile re ati agbelero to n ro, o fi wa dabi eni wi pe ohun ti o n so latari adadasile yi ni pe Islam n wa bukata si awon adadasile yi ati awon agbelero to pamon si Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) kio le pe, ti yio si pari.

Beesi ni Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) sope:

"mo fiyin sile lori ilana ati awijare toye yeke, ti oru re si dabi osan re, enikan koni ye kuro nibe leyin mi ayafi ki o parun" (al mustadrak hala sohihain 1/175).

 

 

 

IDAJO SISE ALEKUN NIBI ESIN OLOHUN PELU NNKAN TI ALLAAHU ATI OJISE KOSE LOFIN

 

Olohun ti ola Re ga so pe:

"بَلَى مَنْ أَسْلَمَ وَجْهَهُ لِلّهِ وَهُوَ مُحْسِنٌ فَلَهُ أَجْرُهُ عِندَ رَبِّهِ وَلاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ" {البقرة/112}

"Bee ni (won ko nii wo inu Ogba idera afi) eni ti o ba ju ara re sile (ninu Islaam) fun Allaahu, ti o si je oluse rere. Nitori naa, esan (ise) re n be fun – un ni odo Oluwa re, ko nii si iberu fun won. Won ko si ni banuje" (al-baqorah:112).

Otumo si: eni ti o ba se afomo awon ise e re fun Olohun ti o si fi okan re dojuko Olohun ti o si tun je oluse daadaa, to n ti sise afomo esin re fun Oluwa nikan, pelu pe ohun sin Olohun pelu ofin Re, awon wonyi nikan sogan ni omo Al – Jannah.

Imam Ahmad gba Hadith wa latodo Abdu Allah omo Mas’huud (ki Allaahu ba wa yonu si) o sope:

(Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) fa ila kan leyinnaa o so pe: Eyi ni ojuona Olohun” leyin naa o tun fa awon ila pupo legbe otun re ati osi, o si tun so pe: Awon wonyi ni awon ojuona pupo, Eesu si n be lojuona kookan kookan ti n pepe si i. leyin naa o ka.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَأَنَّ هَذَا صِرَاطِي مُسْتَقِيمًا فَاتَّبِعُوهُ وَلاَ تَتَّبِعُواْ السُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمْ عَن سَبِيلِهِ ذَلِكُمْ وَصَّاكُم بِهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ") {الأنعام/153}

 

“Ati pe dajudaju eyi ni ona mi ti o je ona taara nitori naa, e tele. E maa se tele awon ona (miran) nitori ki o ma baa mu yin yapa ona Re, iwonyi ni o pa lase fun yin nitori ki e le paya re” (Suratul Al – Ani’aam 153). (Ibn Hibban)

Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) naa tun so pe:

"Tira Olohun lo je ododo ju lo, eyi tio dara ju ninu ilanan ni ilananMuhammad, awon oro to si buruku ju ni awon eyi ti o ba je adadasile, gbogbo agbelero patapata si ni anu, gbogbo anu patapata inu ina ni yio gbe ni lo". (Ibn Khuzaema)

O wa fojuhan kedegbe nibi awon Aayat ati awon Hadith abiyi wonyi titobi i maa so nipa Olohun ati Ojise Re laini imo tabi dida nnkan tuntun sile ninu esin, yala o je ti toro enu ni tabi ti isesi tabi ti adisokan, eleyi ti Olohun ko yonda re ni ise. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"قُلْ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَالإِثْمَ وَالْبَغْيَ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَأَن تُشْرِكُواْ بِاللّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا وَأَن تَقُولُواْ عَلَى اللّهِ مَا لاَ تَعْلَمُونَ "     {الأعراف/33}

“So pe: OHun ti Oluwa mi se ni eewo ni awon iwa ibaje – ohun ti o foju han ninu re ati ohun ti o pamo, ati iwa ese ati ote sise lailetoo, ati biba Olohun wa egbe ti ko si so awijare kan kale lori re, ati siso oro nipa Olohun ni nnkan ti eyin ko nimo nipa re”. (al-ahroof:33).

Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"وَلاَ تَقْفُ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ إِنَّ السَّمْعَ وَالْبَصَرَ وَالْفُؤَادَ كُلُّ أُولئِكَ كَانَ عَنْهُ مَسْؤُولاً" {الإسراء/36}

“Ma se tele ohun ti iwo ko nimo nipa re. dajudaju igboran, iriran ati okan, ikookan awon nnkan won yen ni a o beere nipa re". (Suurah al – isrooh : 36).

Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"أَمْ لَهُمْ شُرَكَاء شَرَعُوا لَهُم مِّنَ الدِّينِ مَا لَمْ يَأْذَن بِهِ اللَّهُ" {الشورى/21}

 “Abi won ni awon orisa kan ti n pase esin kan ni, ohun ti Allaahu ko pa lase". (Suuratul a – s – shuuroo 21).

Gbogbo eni ti o ba da adadasile sinu esin Olohun pelu ohun ti Olohun kose lofin tabi ti Ojise Re kose lofin, latari wi pe n se ohun ti Olohun se ni eewo leto tabi ti n se ohun ti Olohun se ni eto leewo, keferi ni iru eni bee ti ko ba tuba (ronupiwada), ni ijeri si oro ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) nipa oro Olohun ti Ola Re ga ti o wa ninu Surah Taobah bayii:

"اتَّخَذُواْ أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَابًا مِّن دُونِ اللّهِ" {التوبة/31}

“Won mu awon alufaa won (ninu Yehuudi) ati awon alufaa won (ninu Nasaara) ni oluwa leyin Olohun” (Suratuul Taobah 31)

Oso pe: "kii se pe won o maa sin won gan an gan ni pato, bi kose pe ti won ba ti se nkan leto fun won, awon naa o si ti yara gba leto, ti won ba si tun se nkan kan leewo fun won, lojuese naa ni won o tun gba a leewo". (At-tirmidhi)

ileri Iya nla to le koko si ni Olohun se lori isesi awon olutele won lori imaa se ohun ti Allaahu se leewo di eto lodo ara won tabi sise di eewo, ohun ti Allaahu se ni eto. Sheikh Abdul Rahãn omo Saadiy (ki Olohun bani ke) so bayi ninu Itupale Ayat yi ……………… "won yoo maa se lofin, awon oro to tako esin awon ojise Olohun, ti awon omoleyin won o si tun maa tele won, won a si tun maa se aseju nipa gbigbe iyi fun awon Alfa won ati nipa sisin won (awon enii re, ti won n sin Olohun) won yoo ma gbewon tobi pupo won yoo si tun so saare won di ile oosa, ti won yoo maa sin, yatosi Olohun ti won yoo si maa ke pewon tabi maa wa iranlowo si odo won.”

 

 

KINNI ITUMO ADADASILE (BID’HA)

           

Kofi le je pe itumo Bid’ha yi o ye yekeyeke bakannaa ti Sunnah yi o si han siwa kedere. Kinni itumo Sunnah?

Sunnah ni gbogbo nnkan ti Ojise Allaahu (ki ike ati ola Olohun ma ba) ati awon sahabe re duro le lori nibi igbagbo ati ise sise.

Alfa wa Haafiz omo Rojab (ki Olohun bawa ke so wipe: Sunnah ni ona ti a rin eleyi ti o ko titele Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) sinu lakotan, bakannaa itele nnkan ti awon arole afinimona duro le lori nibi awon igbagbo, awon ise ati awon oro – enu, eleyi ni Sunnah ti o pe perepere.

Bee si ni titele Sunnah nibi oro enu, ise ati igbagbo je ohun ti o pondadan, tori pe Allaahu ti Ola Re ga julo so pe:

"لَقَدْ كَانَ لَكُمْ فِي رَسُولِ اللَّهِ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِّمَن كَانَ يَرْجُو اللَّهَ وَالْيَوْمَ الآخِرَ وَذَكَرَ اللَّهَ كَثِيرًا" {الأحزاب/21}

 “Dajudaju awokose rere wa fun yin lara Ojise Olohun, fun enikeni ti o ba n reti (esan) Olohun ati ojo ikeyin. O si n se iranti Allaahu ni opolopo igba". (Suruuah Al – Ahzaah: 21)

 Bakanna, ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) pa awon ijo re lase idunimo ilana re, ati ririn lori ipase re pelu ikose ilapa re lori gbogbo nnkan ti a ba n se, ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so wi pe:

“Mo n so asosile iberu Olohun fun yin, ati gbigbo pelu titele ase, koda ko se wipe oje ojulowo eru ile Habasha, eni ti emi re bagun pupo, yoo ri iyapa enu topo, nipa bayi o dowoyin o lati dunni mo Sunnah mi, ati Sunnah awon arole afinimona, e diromo daadaa, ki e si fi eyin ogan yin dimu sinsin, sisora fun adadasile dowoyin o, tori pe gbogbo agbelero ni adadasile, gbogbo adadasile anu si ni." (Ibn Hibban)

 Sheikh Islam omo Taymiyyah (Ki Olohun ba ni Ke) so wipe:

“Olohun ran Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) si enikookan, omoniyan ati Alujannu, awon ti a fun nita ati awon miran ti a ko fun, lori gbogbo nnkan to jemo esin, ninu ohun ti o pamo tabi ti o han, nibi oro igbagbo ati ilana ofin esin, nipa bayi kosi adisokan igbagbo kan ti Olohun yonu si ayafi adisokan igbagbo ti e, kosi ohun paapa kan, ayafi ona iyege ti e, kosi si ofin ti omoniyan o maa mulo, ayafi ofin ti e, enikankan o si le mo Olohun ninu eda tabi ki o ri iyonu Olohun, tabi ki o wo Al – Jannah, (ile idera) tabi ki o ri aponle latodo Allaahu, tabi ki Olohun mu ni ayanfe re, ayafi ki o je eni ti ntele ilana ijosin Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) nikoro ati nigbangba nibi awon oro – enu, awon ise tohan tabi to pamo, lori ijosin okan ati ti igbagbo ati awon ijosin Ahon pelu awon ijosin alafarase, kosi ayo fun Olohun ayafi eni ti o ba tele ase Re ni koro ati gbangba, to si gba iroyin Re lododo nipataki awon iroyin ohun ti o pamo, to si dunnimo itele ase re lori nkan ti o se loranyan lori eda, gegebi awon ohun to je oranyan ati gbigbe awon nkan eewo ju sile. Eni ti o ba ladisokan eni kan ninu awon eniyan ti o se pe kii mu awon oranyan wa ti won kii si gbe awon nkan eewo ju sile, yala o je nkan toba opolo mu ati idaru opolo, enikeni to ba se adisokan pe eni kan ninu awon wonyi je ore Olohun, oluberu Olohun, o si wa ninu awon ti Olohun maa gbega pelu imo ati igbagbo to n ti boseje pe won o mu awon oranyan wasi sise, ti won kosi gbe awon nkan eewo sile, irufe eni ti o ba di adisokan pe Olohun je ololufe iru awon bee oun naa ti di keferi, to siti gbunri kuro lojuonan esin Islam, ti kosi si ninu awon olujeri pe Ojise Olohun ni Anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun ma ba) bikose pe opuro loje mo Anabi Muhammad lori ijeri re ti o ni si, nitori pe Anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti royin awon ore Olohun fun wa nibamu si oro Olohun pe awon ololufe Olohun ni awon oluberu Olohun ti won si tun je onigbagbo ododo Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"أَلا إِنَّ أَوْلِيَاء اللّهِ لاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ * الَّذِينَ آمَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ" {يونس/ 62& 63}

“Gbo dajudaju awon ore Olohun, ko nii si iberu fun won nibi (iya orun) won ko sin i banuje (lori oore aye)” (Suurah Yuunus : 62-63)

Allaahu ti Ola Re ga tun so pe:

"يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ" {الحجرات/13}

 “Eyin eniyan dajudaju A dayin lati ara Okunrin ati Obinrin. A si se yin ni orile – ede. Orile ede ati iran – iran nitori ki e le mo ara yin. Dajudaju eni ti o ni aponle julo ninu yin ni odo Olohun ni eni ti n paya (Re) ju lo. Dajudaju olumo Alamotan ni Olohun"         (Suuurah al – hujuroot 13)

 Iberu Olohun ni ki eniyan maa tele ase Olohun lori imole ti o wa lati odo Re, leni ti n se afokante ike Olohun, Bakannaa ki eniyan tun maa gbe ese ju sile lori imole bi o ti se wa lati odo Allaahu, ki o maa beru iya Allaahu, ore Olohun kan o le sunmo an ayafi pelu mimu awon oranyan wa, leyin naa mimu awon Nafila (eeni) naa wa. Olohun ti Ola Re ga julo so pe: Eni kankan ninu eru mi ko ni maa sumo mi latari mimu awon oranyan wa, eru mi kosi ni ye tabi ki o gbo pelu ki o maa sumon mi pelu mimu awon Nafilat wa titi ti n maa fi feran re”. Gegebi o se wa ninu Hadithul Ilahiy (qudsiy) to lalafia, Imam Bukharriy lo gba a wa.

 

Itumo “Bidiha” Lakota ni: mimu nnkan ti ko si tele wa saye Allaahu ti Ola Re ga so pe:

"بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ" {البقرة/117}

“Olupile dida awon sanmo ati ile ni (Allaahu)” (al-baqorah:117)

Sheikh Abdul – Rahmãn omo Saadiy (ki Olohun bani ke) so ninu itupale (Tefsiir) Ayat yi pe: "Oluda sanmo ati ile lojuponna dida daradara la i si apejuwe iru re kan t'oti gbawaju". (taiseer al-kreem r-rahmon fi tafseer kalam al-monnan:36)

Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"قُلْ مَا كُنتُ بِدْعًا مِّنْ الرُّسُلِ" {الأحقاف/9}

"So pe : Emi ko ni akoko ninu awon ojise" (al-ahkoof:9)

Sheikh Abdul Rahmãn omo Saadiy (ki Olohun bani ke) so ninu itupale Ayat yi: itumo re ni wipe:

"emi kii se akoko ojise ti yoo koko wa bayin ti e fi wa maa ri ise mi bi nnkan ajoji, ti e fi maa wa tako ipepe mi, awon opolopo ojise ati awon Anabi Olohun ti gbawaju, to se pe mo n fi ipepe mi se ibamu si ipepe won, kinlowa fa ki e maa tako ijise mi?" (taiseer al-kreem r-rahmon fi tafseer kalam al-monnan 725)

Pelu agboye itupale yi, a ri wi pe Adadasile pin si iran meji

1. Alakooko: Adadasile ninu esin: Ohun ni gbogbo ohun ti won ba sese dasile ninu esin tosi yapa si ilana ijosin Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) ati ilanan ijosin awon sahabe nibi adisokan igbagbo tabi ise, eleyi si ni Adadasile to je eewo pelu eri to wa latinu Al – Qu’ran Kareem, Olohun ti Ola re ga julo so pe:

"وَمَن يُشَاقِقِ الرَّسُولَ مِن بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُ الْهُدَى وَيَتَّبِعْ غَيْرَ سَبِيلِ الْمُؤْمِنِينَ نُوَلِّهِ مَا تَوَلَّى وَنُصْلِهِ جَهَنَّمَ وَسَاءتْ مَصِيرًا" {النساء/115}

"Enikeni ti o ba lodi si Ojise (ike ati ola Olohun ko mo ba), leyin ti imona ti foju han si i kedere, ti o tun tele ona ti o yato si ti awon onigbagbo ododo, Awa yoo k'eyin si ire eni bee, Awa yo si mu un wo inu ina Jaanamo. O si buru ni ikangun". (an-nisai:115)

Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

"Gbogbo ijo mi ni yo wo Alujannat ayafi eni ti o ba ko (lati won Al – Jannah), Awon Sahabe beere pe: Ire Ojise Olohun: Taani yoo wa ko? O dahun pe: Eni ti o ba tele mi yo wo Al – Jannah, eni ti o ba yapaa mi irufe eni bee lo ko". (Al-Bukhori)

Sheikh Islam omo Taymiyyah (ki Olohun bani ke) so pe:

“Tori oro to jade ninu Hadith oke yi lofa ki Olohun(ti Ola Re ga julo) pawa lase pe ki a maa se adua nibi gbogbo irun kookan bayii:

اهدِنَا الصِّرَاطَ المُستَقِيمَ صِرَاطَ الَّذِينَ أَنعَمتَ عَلَيهِمْ غَيرِ المَغضُوبِ عَلَيهِمْ وَلاَ الضَّالِّينَ

“Fi ese wa rinle sinu (Islaam), ona taara, ona awon ti o se idera fun yato si (Ona) awon (Yahuudi) ti o binu si ati (Ona) awon (Nasaara), Olusina” (Suurah Faatihah: 7)

Awon ti Olohun n binu si ni awon ti won mo ododo sugbon ti won n se ohun toyapa si ododo. Bakannaa awon to sina si ni awon to n sin Allaahu lai ni imo pelu wi pe won tun mo pe iyen yapa si Al – Qur’an ati Sunnah.”

Bakanna, Awon Adadasile ninu esin naa tun pin si meta:

Alakooko: Awon adadasile to so eniyan di keferi to gbe eniyan jade kuro ninu Islam, gegebi awon Bidiha to sopo mo adisokan igbagbo, bii eni ti o n pa nnkan fun ohun miran to yato si Olohun, ati bii awon ti won maa n yipo Saare ati bii awon ti maa n pe nnkan miran to yato si Olohun, ti won si maa n wa atileyin lowo nkan mii yato si Olohun lori nnkan ti enikan kan o kapa lati se, ati awon nnkan to tun jo awon nnkan ti a so soke wonyi, ninu awon ijosin to se pe ko leto ki a gbe fun nnkan kan miran yatosi Olohun. Olohun ti Ola re ga julo so pe:

"قُلْ إِنَّ صَلاَتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ # لاَ شَرِيكَ لَهُ وَبِذَلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَاْ أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ" {الأنعام/163}

“So pe: Dajudaju irun mi, eran mi, (ti mon pa) isemi aye mi ati ikumi ti Olohun, Oluwa gbogbo eda. Ko si orogun fun – un iyen ni won pa mi lase re, emi si ni akoko awon Musulumi (ni asiko temi).” (Suurah al – aniam :163)

Eleekeji: Awon Adadasil ti ko so eniyan di keferi, sugbon ti won je ategun si eyi ti o le soniyan di keferi, Gegebi i maa mo'le sori saare, ati i maa see loso ati i maa kirun ati i maa sadua nibi saare. Idi niyi ti ojise Olohun fi ko fun ijo re pe won ko gbodo ma paara idi saare oun, fun iberu ki won o ma pada sodi nnkan ti won yoo maa sin leyin Olohun. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

"E ma so ile yin di saare, e si maa so saare mi di aaye tee maa pooyi fun ijosin, ki e si maa se Asalaatu fun mi, Asalaatu yin ti e ba se yoo maa ba mi nibikibi ti e ba wa". (Abu Dawud)

Eleketa: awon Adadasil ti idajo re je ese, bi ki eniyan pinnu lati maa fe iyawo tabi ki o loko, bii ki eniyan maa gba aawe lojoojumo lati asiko Fajri (asuba) di Magrib (iwo orun), bi ki eniyan maa se Nafilat ni gbogbo oru lo gbere, ati awon ohunkan miran ti o tun jo eyi. Nitori eri Hadith Annas omo Malik (ki Olohun bani yonu si i) ti o so pe:

"Awon odomokunrin bii mesan kan waa ba Ojise Olohun nile, won wa lati waa bere isesi ijosin Ojise Olohun, nigba ti won so odiwon Ijosin Ojise Olohun fun won, o dabi eni pe awon Okunrin foju kikere wo ijosin Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) won ba so pe: Kinni ipo ti tiwa legbe ti tanabi Enikan ninu won ba so pe: Emi ni temi, maa maa fi gbogbo oru yan Nafila ni lojoojmo, Elomiran so pe: Emi yoo maa fi ojoojumo gba aawe lati Fajri di Magrib ni, mi o si ni fi Ojo kan sile lai gba aawe, Elomiran tun so pe: Emi n temi maa yera fun ibalopo obinrin mi o ni feyawo, Ojise Allaahu (ki ike ati ola Olohun ma ba) ba de si aarin won o so fun won pe: Se eyin le n soro bayi bayi? Mo fi Olohun bura, emi ni mo beru Olohun julo, ti mo si paya Re julo, sugbon emi maa n fi abala kan oru yan Nafilat ni, ti mo si maa n fi abala yoku sun, mo si maa n fi awon oja kan gba aawe ti maa si fi awon to seku ninu ose sinu lai gba aawe, mo si maa n feyawo, eni toba ko lati tele ilana ijosin mi, ki i se ara a mi". (Al-Bukhari ati Muslim)

nibiyi lo ti foju han pe eni ti o ba n sin Olohun pelu nnkan ti Olohun ko se lofin tabi ti Ojise re (ki ike ati ola Olohun ma ba) ko se nise tabi ti awon arole afinimona ko se, iru eni bee ni Aladadasile, nitori oro Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti o so pe:

“Mo n so asosile fun yin pelu iberu Olohun ati gbigbo pelu titele ase olori, koda ko se pe eru ile Habasah ponmbele ni alase yin, eni ti emi re ba si gun yoo ri awon iyapa enu to po, odo wo yin lati diro mo ilanan ijosin mi, ati ilanan ijosin awon arole afinimonan, e diro mo daradara, ki e si fi eyin ogan yin dimu sinsin, awon adasile dowo yin ki e sorafun o, tori pe gbogbo agbelero ni adadasile, gbogbo adadasile si ni anu”. (soheeh bin hiban 1/178, hadeeth 5)

2. Iran keji ni adadsile ninu nkan aye: Iyen ni gbogbo adadasile nipa oro ile aye, eleyi ti ko ni ibasepo kankan pelu ofin esin, bi awon adadasile awon nnkan tuntun amayederun, ati awon ohun ti o tun jo o, eleyi leto won ki se Adadasile ninu ofin esin, botile je pe won n pe e ni adadasile ninu ede siso, eleyi si ki Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ni ki a sora fun, tori pe ipile fun awon isesi ati oro nnkan sise laye, ohun eto loje lopin igba ti eri to tako ko ba si, Ibasepo eda naa si fara pe eleyi, eyi ti o ba ba ofin esin mu iyen ni ajosepo tio ni alafia, eyi ti o ba yapa si i, iyen ni ajosepo ti o dara, won kii si i pe iru re Adadasile ninu esin tori pe kosi ninu esin.

 

 

OJU TI OFIN ESIN FI WO ADADASILE NINU ESIN

           

Ti a ba mo wipe ijeri pe Muhammad je Ojise Olohun ntumo si: titele ase re (ki ike ati ola Olohun ma ba) lori nnkan to ba pawa lase, ati gbigba iroyin ti o ba mu wa lododo, ati jijina si nnkan to ba ko fun wa, ati ki a maa ri pe a n sin Olohun pelu ohun ti o se lofin , yio han siwa kedere pe oranyan ni ki a ko lati fi aaye gba agbelero ati adadasile ninu esin Olohun ti Ola Re ga. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"فَلْيَحْذَرِ الَّذِينَ يُخَالِفُونَ عَنْ أَمْرِهِ أَن تُصِيبَهُمْ فِتْنَةٌ أَوْ يُصِيبَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ" {النور/63}

“Nitori naa, ki awon ti n yapa ase re lo sora (won), nitori ki idaamu ma baa de ba won tabi nitori ki iya eleta maa baa je won.” (Suratul Nuur: 63)

Ojise Allaahu (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

“Enikeni to ba da adadasile ninu esin Islam wa yii, ti nnkan naa si je pe kosi ninu esin teletele, nnkan naa ti di ibaje, eleyi ti a o dalu eni to se e laye, tori pe a o ni kakun esin.” (soheeh al-bukhoriy 2/959, hadeeth 2550)

Hudhayfa omo Yammaan ki Olohun bani yonu si so pe:

"Awon eniyan maa n wa lati bi Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) nipa ohun todara todara, sugbon emi maa n saaba bi ni ohun to buru to buru fun iberu ki n ma fi le loo ko sinu re. Mo pe Ojise Olohun, mo ni ire Ojise Olohun: Awa je eni ti iwa buburu po fun ni igba aye aimokan, eyi si ni o fa ki Olohun mu oore nla yi wa. Nje aburu tun n pada bowa leyin Oore yi bi? O dahun pe: Beeni. Mo tun bi leere pe: Nje oore tun maa wa leyiin aburu yi bi? O tun dahun pe: Beeni, subgon eefin dudu abawon yoo papo mo oore naa, mo tun beere wipe kinni eefin abawon yi tumo si? O dahun pe: Awon eniyan kan ti won o ma lo ilanan ijosin to yato si ilana ijosin temi, won yoo maa lo imonan toyato si imonan temi, oori awon ilanan ijosin to ba ofin esin mu ati eyi totako ofin esin lara won".

Mo tun bi lere pe: Nje aburu tun maa sele leyin oore yi bi? O dahun pe: “Beeni, awon olupepe si awon ojuona ina Jahanamo kan yoo waye, eni toba dawon lohun won o ju sinu awon ojuonan inan yii” Mo tun pe iwo Ojise Olohun: Royin won fun wa? O dahun pe: Awon ni awon eniyan ninu wa ti won o maa se bii wa ni irisi ni gbangba sugbon ti won yoo yato siwa gedegede nibi ise won nikoro, won yoo ma so iru oro tawa naa maa n so, mo tun ni iwo Ojise Olohun: Kinni imoran ti o le gbami ninu iwoye re, ka ni pe akoko naa bami laye? O dahun pe: Ri wi pe o dunnimo i maa wa laari ijo Musulumi to dunnimo Al – Qu’ran ati Sunnah daradara ati ko dunnimo bibe pelu Imama (asiwaju) awon Musulumi, mo tun beere pe: Ti won o ba ni ijo nko bakannaa ti won o tun ni Imam? O dahun pe : Ri pe o yera fun awon ijo orisirisi ti won o dunnimo Al – Qur’an ati Sunnah koda ko se pe o maa feyin ge idi igi je lounje fun yiyera to maa yara fun won (Itumo eleyi ni ogongo iyerafun) titi tiku yoo fi de ba o ti yoo fi pa o lori isesi yi". (soheeh al-bukhoriy: 3/1319, hadeeth 3411)

Latodo Abdu Allah Omo Mas’hood (ki Olohun bani yonu si) so pe: Ojise Olohun (ike ati ola Olorun ko ma ba) so pe: "Emi ni eni ti yoo koko de ibi abata Al – Haud, Olohun o wa fi awon eniyan kan han mi, leyinnaa won yoo gbunri won kuro nibi abata Al – Haudu yi lati jawon kuro lona odo mi, maa maa wa so pe: Oluwa mi awon ijo mi niyi, awon ijo mi niyi, won yoo ba so fun mi pe o mo ohun ti won da ni adadasile leyin re". (soheeh al-bukhoriy: 5/2404, hadeeth 6205)

Annas Omo Malik (Ki Olohun bani yonu si) so pe: Ojise Olohun (ike ati ola 0lohun ko mo ba) so pe: Dajudaju Olohun ti di gaga gbigba (Tutuba) ironupiwada mo oni (Bidiha) adadasile. (Al-Bayhaqi lo gba wa)

Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti salaye pe awon fitina yio sele leyin ti oun bakuro laye ati wipe didiromo Al – Qur’an ati Sunnah Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) nikan ni yio je ona abayo. Tori naa ko si nnti nje agbelero ati adadasile ninu esin.

Abu – Huroira (Ki Olohun bani yonu si) so pe: Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

"Awon fitina kan maa sele, eni to ba joko yoo loore ju eni toba duro lo, eni to ba duro latari eyi yoo loore ju olufeserin lo, olufeserin yoo loore ju oluse iposese lo, eni to ba sa ipa lati dekun awon fitnah yo le bori won, eni to ba si ri ibusasi tabi ibusadi kofi se isadi kuro nibi awon fitinah yi". (bukhori ati muslim)

 

 

 

DIE LARA AWON ORO TI AWON ALFA ATI AWON TO TUMO QUR’AN SO NIPA BI WON SE FENU ABUKU KAN AWON ADADASILE

           

Umar omo Khattob (Ki Olohun bani yonu si) so pe:

“Odowo yin lati sora fun awon ti won kan maa n fi irori tiwon lasan se idajo esin, tori pe ota Sunnah ni won je, won ti kagara lati tele awon (Hadith) oro Ojise Olohun bakannaa won tun kagara lori siso Sunnah, won ka n fi irori won nikan so oro nipa esin ni. Nipa bayi won ti sonu, won si tun n so awon elomiran nu ni.”

Omo Abbas (Ki Olohun bani yonu si) so bayi nigba ti oun tumo Ayat yii “Olohun ti Ola Re so pe:

"يَوْمَ تَبْيَضُّ وُجُوهٌ وَتَسْوَدُّ وُجُوهٌ" {آل عمران/106}

“Ni ojo ti awon oju kan yoo funfun awon oju kan yo si dudu” (Suurah aali imroons: 106)

E ri awon toju won maa funfun ni awon to tele Sunnah ati Jom’ah Musulumi ati awon onimimo, sugbon awon toju won maa dudu ni awon Aladadsil, ati awon eni anu.”

Umar omo Abdul Azeez (Ki Olohun bani ke) so pe:

“Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti fi ilanan ijosin le le, Awon oludari afinimona naa ti fi awon ilanan ijsoin lele, gbigba lati se amulo awon ilanan ijosin won lo tumo si pe agba Qur’an gbo lododo, bakannaa, a si pe titele ase Olohun, agbara si ni eyi je fun esin Olohun, kosi leto fun enikeni lati yii pada, bakanna ko leto ki a woye pe ohunkan to yapa si ilanan ijosin Ojise Olohun la o maa se, nipa bayi eni toba kose ilanan ijosin Ojise Olohun ni Olumonan, eni toba si wa ikunlowo pelu e ni eni ti won ranse, eni ti o ba yapa eyi, ti o wa tele ojuonan miran yato si ojuonan awon olugbagbo ododo Olohun yoo tusile ki o loo gba ikunlowo lowo awon olugbowo miran yato si Olohun, Olohun yoo si fi kona Jahannamo, iyen si je ibupadasi to buru ju.”

Al-fodeel Omo Iyyahd (Ki Olohun bani ke) so pe:

“Ti o bari Aladadsile kan lojuona, tete yara gba ojuonan miran, kosi ise kan tole gbe (Onibidiha) Aladadsile ga niwaju Olohun, enikeni toba ran Aladasile lowo iru eni bee ti se iranlowo lori atile wo esin Islam.”

Sufyaan Thaoriy (Ki Olohun bani ke) so pe:

“Iblis (esu) feran ki o gba ona Adadsile si eniyan lona ju ona Iyapa ase Olohun lo, nitori pe eni ba da ese, ti o yapa ase Olohun, yoo (tuuba) ronupiwada kuro nibe, sugbon Aladasile ki i (tuuba) ronupiwada kuro nibi Bidiha sise.”

Omo Quayyum (Ki Olohun bani ke) so pe:

“Ti awon kan ba ti kairoju pelu (Bidiha) Adadasile, won yio gba awon kan naa kuro nibi Sunnah ni.”

 

 

 

AWON IRUJU TI WON KODANU NIBI I MAA SO ADADASILE DI OHUN TO DARA NINU ESIN

           

Awon ti o nimo nipa esin maa n fi Hadith ti a fe so yi se eri fun atile tan Adadasile ati Agbelero ka inu esin.

Oro ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti o so pe: "Enikeni ti o ba la ona daradara kan ninu Islam, yoo maa gba esan lorii re, ati lori gbogbo eni ti o ba samulo re leyin iru eni yen, la i je wi pe esan kankan yoo dinku ninu esan tawon eni naa, bakannaa eni ti o ba la ojuona aida kan ninu Islam eru ese re yi o maa be lorii re ati lori awon miran to ba fi sise lai se pe won yio din nnkankan ku nibi eru – ese awon wonyi". (soheeh muslim: 2/704, hadeeth 1017)

Idahun si eleyi ni wi pe eni ti o ba so pe: Eni ti o ba la ona daradara kan ninu Islam”. A o maa ran leti wi pe sebi Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) naa lo tun so pe: Gbogbo Adadasile ni anu. Kosi rorun ki Ojise Olododo ti a maa n gba oro re lododo ki o so oro ti ikan o maa pe omiran niro, tabi ti ikan yoo maa tako omiran, nipa bayi alaye wi pe awon Hadith mejeeji yi ko dojuru ni pe Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe: Enikeni ti o ba la ona daradara kan ninu Islam. Awon Adadasile kosi ninu Islam bakannaa,Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) tun so pe: " eni bafi onan daradara kan lele", Adadasile kosi si ninu ona daradara ati pe iyato Sunnah ati Bid’ha ni pe: Eniti o ba la ojuonan Sunnah tumo si eniti o ba ta Sunnah kan jii, ti o si je Sunnah ti o ti nbe teletele, ti Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) si pase mimulo re, yala o je oro enu, tabi ise, tabi ohun ti o ri pe awon ka n se ti kosi ko fun won ti iru Sunnah nan ti waa pare tabi ti awon eniyan ti gbagbe re.

Ohun tosokunfa Hadith naa tun kanpa mo itumo ti a so yii, ohun naa ni itan awon eniyan to po die kan ti won waa ba Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti won wa ninu isesi inira tole koko, ti Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) si pepe fun itore aanu fun won, Okunrin kan ninu Ansoor ba de leni ti o gbe fadak ekunwo to tesunwan siwaju ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) nipa bayi Oju Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) kun fun imole idunnu ati ayo fun ohun ti okunrin yi se, o fi wa so pe: Enikeni ti o ba la onan to dara kan ninu Islam, yoo gba esan lori re, yoo tun gba esan lori gbogbo eni to ba n samulo re titi di ojo Igbende. (Sahih Muslmi)

Nibiyi loti wa yewa si wipe lila ona inu Hadith yi tumo si lila onan ise sise lati samulo ki i se lati dida ilana ijosin tuntun sile, tori pe lila ona ijosin tuntun je (eewo) ohun ti wonko fun wa lati se “Gbogbo Adadasil anu ni”.

Sheikh Abdul Azeez bn Baaz (Ki Olohun bani ke) so pe:

“Oro Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) kole tako ara won. Eleyi si ni oro apanupo gbogbo awon onimimo. Nipa bayi o mo wipe erongba Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) nibi Hadith yi ni tita (Sunnah) ilana ijosin ji ati fifi SUnnah han. Fun apeere ki onimimo maa gbe ni ilu ti awon eniyan o ti mon Al – Qur’an Kareem tabi ti won o mo Sunnah Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti o wa ta Sunnah ji nibe latari pe o joko tiwon o si n kowon ni Al – Qur’an ati Sunnah, tabi o ko awon onimimo wa sibe lati maa kowon.

Tabi ki onimimo kan wa ni ilu ti awon eniyan maa fa irungbon won tabi ki won ge irungbon won, kowa pawon lase pe kiwon o maa fi irungbon won sile, ki awon naa sigba lati se bee. Iru eni bee tita Sunnah nla yi ji ninu ilu yen ti won o ti mo iyen tele. Iru Esan ti eni ti o se sababi imona fun ba gba gele ni oun naa yoo gba. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti so pe:

"E maa ge tubomu, e maa fi irungbo sile ki e fi le yato si awon osebo".

Ti awon eniyan ba ri iru onimimo yi ti o fi irungbon re sile, ti o si n pepe lo sibe, won yoo tele, nipa bayi o ti ta Sunah ji latara won, tabi gbogbo nnkan miran to ba tun jo eleyi ninu ijosin ati awon idajo ti a mo ninu esin ti aimokan fi kuro fun awon ilu die kan tabi awon idile die kan, iru eni ti o ta a ji laariin won ti o fi fonka laarin won ni won yoo ma so pe: O la onan daradara kan ninu Islam” Iyen si tumo si pe o safihan idajo Islam, iru eni bee yoo wa di eni ti o la ona daradara kan ninu Islam, ki i se pe ohun ti won gba lero ni dida Adadasil ninu esin eleyi ti Olohun o si yonda lati se be.

Gbogbo Adadasile patapata si ni anu fun oro ti ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so ninu Hadith tolalaafia yii:

"O dowo yin ki e sora fun Adadasile, tori pe gbogbo Agbelero ni Adadasile, gbogbo Adadasile patapata sini anu".

Bakanna awon (Onibid’ha) Aladadsile maa n fi oro Umar ti a fee so yi se eri fun titanka awon Adadasile ti won n se yi. Nigba Umar (Ki Olohun bani yonu si) o ko awon eniyan jo fun irun Tarawihi inu Romadan ni Janmo lapapo, o si yan Imam kan ki o siwaju irun, o waa so pe : (Bid’ia eleyi dara).

Tori pe o mo wipe irun Tarawih ni ipile ninu ofin esin, kii se pe Umar lo sese da eyi sile nitori pe ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) gan – an naa see, enu wi pe o gbe kiki i ni janmo ju sile fun iberu wi pe ki Olohun ma pada so irun Tarawih di oranyan fun (Ummah) ijo re, nipa bayi erongba Umar (Ki Olohun bani yonu si) pelu gbolohun to ti so pe Bid’ha kii se Adadasile eyi ti esin se lewwo rara, Adadasile oro inu ede lasan ni.

Leyinna awon Sahabe(ki Olohun yonu si won) won wa lori kiki be leyoyo loju aye Annabi-ki ike ati ola Olohun ma ba- ati leyin iku iku re ninu Masalasi Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- titi Umar(ki Olohun yonu si) fi ko won jo si eyin imamu kan leyin iku Anabi-ki ike ati ola Olohun ma ba- nigbati o se pe won ti ni ifokanbale kuro nibi ohun ti Ojis Olohun-ki ike ati ola Olohun ma- nibi sise ni oranyan lori awon ijo re e. O wa so oro re to lo bayi pe: (Bidi'ah yi ma dara o). O ri mu ninu oro yi pe dajudaju irun tarawihi ni ipile ninu Shariah ki se Umar(ki Olohun yonu si) ni o se adadasile re nitoripe Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun ma ba- ki irun tarawihi ni jama, leyinna o fi kiki re ni jama sile niti iberu ki Olohun ma se ni oranyan lori ijo re e. Erongba Umar(ki Olohun yonu si) pelu gbolohun Bidiah ni adadasile ninu ede ki i se adadasile ninu ofin Shariah.

 

 

OJU TI OYE KIA FI WO ALADADASILE NINU ESIN

 

Olohun ti Ola Re ga so:

"اتَّبِعُوا مَا أُنْزِلَ إِلَيْكُمْ مِنْ رَبِّكُمْ وَلَا تَتَّبِعُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ قَلِيلًا مَا تَذَكَّرُونَ (3)" (الأعراف:3)

"E tele ohun ti won sokale fun yin lati odo Oluwa yin, ki e si ma se tele awon ore ayo kan leyin re (lori iyapa) die ninu igba ni efin se iranti" (al-ahroof:3)

 Aladadasile ko moribo nibi nnkan ti a fe so yi, ninu ko je pe aimokan lofa sise Adadasile re yi, ti Adadasile kosi han tabi fonka, eleyi ni eni ti won o ko, ti won o salaye fun pelu eri lati inu Al – Qur’an ati Sunnah, wipe ise re ti baje, ati pe ohun ti oun se ti yapa si ofin esin. Tabi ki o je pe Adadasile re wa lati ibi ife – inu ati igbunri kuro nibi ododo, irun eni yi ni a o maa ran leti oro Olohun, ti a o si maa fi ileri iya Olohun seruba a, ti a o si maa salaye fun – un pelu eri lati inu ofin esin wi pe ori ibaje lo wa, a o si maa fi ogbon ati oye pelu isiti ti o rewa ba soro, toba tun wa ko jale, ti o sagidi ti o si taku sori Adadasile re o ti wa di dandan ki a salaye pe ori ibaje nla lo wa, pelu idajo eri ofin esin latinu Al – Qur’an ati Sunnah. A o si sora fun – un, a o tun sora fun Adadasile re yi kofi le jepe awon eniyan miran naa o jinna si i, ti won o si sa fun, toripe Adadasile ko ni se nnkankan fun Aladadasile bikose pe yoo sodi keferi sise, lofi je dandan ki a maa yan Aladadasile lodi leyin ti won ti gbanimoran, tiwon si se isiti fun – un, sugbon ti o ba tun taku lori nnkan ti n se yii. Toba je Adadasile ti ko to eyi to le so eniyan di keferi, ti a ba ri pe atunse le waye nibi yiyan – an lodi, a o yan – an lodi, sugbon ti a ba ri pe kole si atunse kankan nibi yiyanlodi, a ko ni yan an lodi, idi ni pe ki iyen ma sokunfa ki Eesu fi ran – an lowo, ati pe boya latari gbigba a nimoran lemolemo le je ki o gbe nnkan ti oun se yii, ti o yapa si ilana ofin esin ju sile. nitori wi pe Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Ko leto fun Musulumi kan ki o yan omo – iya re lodi koja ojo meta.” (soheeh bukhoriy:5/2253, hadeeth:5718)

Ki a gba gbogbo Adadasile tofoju han, ki asi salaye aida re pelu eri ofin esin latinu Al – Qur’an ati Sunnah, ohun ni ojuona ti awon enire isaaju inu ijo yi rin, ki a si salaye ati ki a gba oro Aladadasile danu komo lori awon onimimo nikan, bikose pe o je dandan fun gbogbo eniti o bari i pe Adadasile ninu esin Olohun koni eri latinu Al – Qur’an oro Olohun tabi Sunnah Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) eleyi toni alaafia, ti o ba je eni ti o lagbara lati salaye, ki o salaye, bi o ba lagbara eyi, aje wipe opandandan fun o ki o gbe ise yen fun awon onimimo oluberu Olohun, ti won lagbara ati salaye, awon ti yoo gba a danu ti won yio si fidi ibaje yi mule pelu awijare eri to ye kooro pe awon Adadasile ninu esin je ibaje.

 

 

AWON OHUN TO NJE KI AWON ADADASILE ATI AWON AGBELERO HAN

 

1.         Jijinna si titele ofin Allaahu ati yiyonu si awon ofin miran yato si ofin Olohun. Olohun ti ola re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ أَطِيعُواْ اللّهَ وَأَطِيعُواْ الرَّسُولَ وَأُوْلِي الأَمْرِ مِنكُمْ فَإِن تَنَازَعْتُمْ فِي شَيْءٍ فَرُدُّوهُ إِلَى اللّهِ وَالرَّسُولِ إِن كُنتُمْ تُؤْمِنُونَ بِاللّهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ ذَلِكَ خَيْرٌ وَأَحْسَنُ تَأْوِيلاً" {النساء/59}

“Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (ase) Olohun, e tele (ase) Ojise ati awon alas ninu yin. Ti e ba yapa enu si kini kan, eseri re si (oro) Allaahu ati (oro) Ojise. Ti e ba ni igbagbo ododo ninu Allaahu ati ojo ikehin” (Suura Nisaa: 59)

2.         Jijinaa si titele Sunnah ati yiyan Sunnah lodi, igbakigba ti Musulumi ba ti le jinna si Sunnah yoo sumo Adadasile si pekipeki, ohun ti yio ro Musulumi loro kuro nibi agbelero ati Adadasile n be ninu Sunnah (awon oro Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) awon ise re ati awon ohun ti ko sise re tosi ri awon eniyan ti won n see). Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

"Mo ti fi ohunkan meji kan sile si aarin yin laelae eko le sina mo leyin ti e ba n tele awon nnkan mejeeji naa, awon naa si ni: Al – Qur’aan ti i se oro Olohun, ati Sunnah mi". (Al-Mustadrak 'ala As-sahihain).

3.         Gbigbe Al – Qur’an sile pelu yiyan lodi, ati aironu jinle lori oro Al – Qur’an, ati gbigbe iranti Olohun ju sile, ati ikagara lati gbo esin ye, Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"وَمَن يَعْشُ عَن ذِكْرِ الرَّحْمَنِ نُقَيِّضْ لَهُ شَيْطَانًا فَهُوَ لَهُ قَرِينٌ" {الزخرف/36}

“Enikeni ti o ba gbuuri kuro nibi iranti Olohun Ajoke aye, A maa yan esu kan fun – un, Oun si ni alabaari n re.” (Suurah Zukhruf :36)

4.         dida ododo pada ati a i gba ododo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِذَا قِيلَ لَهُ اتَّقِ اللّهَ أَخَذَتْهُ الْعِزَّةُ بِالإِثْمِ فَحَسْبُهُ جَهَنَّمُ وَلَبِئْسَ الْمِهَادُ" {البقرة/206}

 “Ati pe nigba ti won ba so fun un pe: Beru Olohun, igberaga yo si mu un da ese si, nitori naa, ina jaanamo to fun (ni esan, ibugbe naa si buru)” (Suurah al – Baqorah: 206)

5.         Mimu awon alaimokan ati awon to ti sonu ni Alfa. Anobi (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Olohun koni fa imo yo lara awon eru, sugbon yio gba kuro pelu gbigba emi awon onimimo, titi ti ko fi ni seku onimimo kan lori ile titi ti awon eniyan o fi maa wa fi awon alaimokan se olori, ti o fi je pe won o maa dajo esin la i ni imo nigba ti awon eniyan ba beere idajo esin kan lowo won, nipa bayi won yoo sonu, won yoo tun maa so awon elomiran nu.” (soheeh bukhoriy:1/50, hadeeth 100)

6.         Diduro lori wiwa agboye esin si ibi awon tira nikan ati gbigbe gbigba imo latowo awon Alfa Oluberu Olohun ju sile. Idi niyen ti won fi maa n sope: Eni ti o ba je pe tira re nikan ni Alfa re, Asise re yio po ju eyi ti o baa mu lo) bakannaa kika awon tira ti o ruju, ni agbegbe awon tio ko tabi ohun tio ko sinu, Bii ru tira ti Umar Omo Khattab mu waa ba Ojise Olohun lojo kan, Umar ni oun gba tira naa lowo awon Yahuudi ati Nasooro ni, Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba) ba kaa o si binu, leyinna o so pe:

”Se e fe maa da ara yin laamu nipa esin yin ni, ti e o fi maa wa gba imo lati nu tira miran yato si tira tiyin, bakanna ti e o si maa gba imona latowo Anabi miran to yato si Anabi tiyin, iwo Omo Khattab, o ni mo fi Olohun to ni ikapa emi mi bura mo ti mu ilana ijosin to ye yekeyeke ti i se Islam waa bayin, nipa bayi e mo bi awon Yahuud ati Nasoora ni nnkankan, ti won o fi maa wa royin nnkan ododo fun yin, ti eyin o maa wa peniro, tabi kiwon o maa royin iro fun yin, ki eyin o maa wa pe lododo, mo fi Olohun to ni ikapa emi mi bura, ti o ba je pe Anabi Musa (ki ike ati ola Olohun ma ba) gan – an ba wa laye bayi ni ko nii se nnkankan ayafi ki o tele mi." (Ahmad lo gba wa)

7.         A i fon imo to lalaafia toye kooro kaa kiri, latara didake awon Alfa, ati pipa imo mora. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"إِنَّ الَّذِينَ يَكْتُمُونَ مَا أَنزَلْنَا مِنَ الْبَيِّنَاتِ وَالْهُدَى مِن بَعْدِ مَا بَيَّنَّاهُ لِلنَّاسِ فِي الْكِتَابِ أُولَئِكَ يَلعَنُهُمُ اللّهُ وَيَلْعَنُهُمُ اللاَّعِنُونَ*إِلاَّ الَّذِينَ تَابُواْ وَأَصْلَحُواْ وَبَيَّنُواْ فَأُوْلَئِكَ أَتُوبُ عَلَيْهِمْ وَأَنَا التَّوَّابُ الرَّحِيمُ " {البقرة159/160}

“Dajudaju awon ti n da so bo ohun ti A sokale ninu eri ododo ati imona, leyin ti A ti salaye re fun awon eniyan sinu Tira, awon wonye ni Allaahu n sebi le. Awon olusebi tun n sebi le won. Afi awon ti won ronu piwada, ti won si se atunse (Ise aburu owo won), ti won si s afihan ododo (ti won ti daso bo), nitorinaa awon won yen ni Emi yoo gba ironupiwada won. Emi ni Olugba – ironupiwada, Alaaanu”. (Suurah al Barorah: 159 – 160)

8.         Sise aseju nibi esin. Iye si ni awon ohun to sokunfa hihan ebo ati Adadasile ju lo. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) se pe:

”O dowoyin lati maa se aseju lori esin tori pe ohun ti o koparun ba awon eni isiwaju ni, aseju won lori esin." (Ibn Hibban lo gba wa).

9.         Ki eniyan maa gbara le idajo opolo araa re nipa oro esin. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ وَلاَ مُؤْمِنَةٍ إِذَا قَضَى اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَمْرًا أَن يَكُونَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ مِنْ أَمْرِهِمْ وَمَن يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَقَدْ ضَلَّ ضَلاَلاً مُّبِينًا" {الأحزاب/36}

“Ko to fun onigbagbo ododo lokunrin ati onigbabo ododo lobinrin nigba ti Allaahu ati ojise Re ba ti pase n kankan, lati ni esa (oro miiran0 fun oro ara won. Ati pe ni eni ti o ba yapa (ase) Allaahu ati (ase) Ojise Re dajudaju o ti sina ni isina ponbele.” (Suurah al – hazaab 36)

10.      Titele ife – inu ati ife aniju si awon oro aye ati mimaa le oro aye lati kojo. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"أَفَرَأَيْتَ مَنِ اتَّخَذَ إِلَهَهُ هَوَاهُ وَأَضَلَّهُ اللَّهُ عَلَى عِلْمٍ وَخَتَمَ عَلَى سَمْعِهِ وَقَلْبِهِ وَجَعَلَ عَلَى بَصَرِهِ غِشَاوَةً فَمَن يَهْدِيهِ مِن بَعْدِ اللَّهِ أَفَلاَ تَذَكَّرُونَ" {الجاثية/23}

“o ri eni ti o so ife – inu re di Olohun re, ti Allahu si si i lona pelu imo (ti o mo nipa re siwaju iseda re pe koni pada tele imonan) ti o si fi edidi di igboran re ati okan re, ti o tun fi ebibo bo oju re. Tani o maa fi onan mon leyin Olohun? Se e o nii lo isiti ni?” (Suurah – al – jaathiyah: 23)

11.      Eyemeya ti ko dara, ati i maa tele irori elomiran ti ofin – esin ti de pe kose tele, pelu i maa gbarale itele afoju lori oro esin, la i se pe eyi ti a mo pa lori imo tabi imonan ododo, ati a i maa seri idajo oro sinu Tira Olohun ati Sunnah ojise re (ki ike ati ola Olohun ma ba) Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّبِعُوا مَا أَنزَلَ اللّهُ قَالُواْ بَلْ نَتَّبِعُ مَا أَلْفَيْنَا عَلَيْهِ آبَاءنَا أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لاَ يَعْقِلُونَ شَيْئاً وَلاَ يَهْتَدُونَ {البقرة/170}

“Ni gba ti won ba so fun won pe: E tele ohun ti Olohun sokale, won a wi pe: Rara, Awa yoo maa tele ohun ti a ba lowo awon baba wa, se (ohun ti wan yoo maa so niyen) ti o si je pe awon baba won ko ni oye kan (nipa esin), won ko si monan.” (Suurah Al – Baqarah 170)

12.      Riropomo ati jijoko ti awon eniyan buruku ati awon obileje Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

وَيَوْمَ يَعَضُّ الظَّالِمُ عَلَى يَدَيْهِ يَقُولُ يَا لَيْتَنِي اتَّخَذْتُ مَعَ الرَّسُولِ سَبِيلاً {الفرقان/27} يَا وَيْلَتَى لَيْتَنِي لَمْ أَتَّخِذْ فُلاَنًا خَلِيلاً {الفرقان/28} لَقَدْ أَضَلَّنِي عَنِ الذِّكْرِ بَعْدَ إِذْ جَاءنِي وَكَانَ الشَّيْطَانُ لِلإِنسَانِ خَذُولاً {الفرقان/29}

“(Ranti) ojo ti alabosi yoo ma je ika owo re mejeeji, o si maa wi pe: Yee emi iba ti to onan (Ola) pelu Ojise. Egbe mi o, yee Emi iba ti mu lagbaja ni ore ayo. Dajudaju o ti si mi lonan kuro nibi Al – Qur’an leyin ti o dewa bami. Dajudaju esu je alabosi fun omoniyan” (Suurah al-furqoon: 29)

13.      Gbigbe i maa panilase daadaa ati mimaa ko fun ni nibi aida sile. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"وَلْتَكُن مِّنكُمْ أُمَّةٌ يَدْعُونَ إِلَى الْخَيْرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَأُوْلَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ" {آل عمران/104}

“KI o maa be ninu yin, ijokan ti o maa pe (awon eniyan) si ibi ise rere. Won yoo maa pase sise daadaa. Won yi o si maa ko sise aidaa. Awon won yen sini olujere.” (Suurah al – imroon: 104)

Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Kosi Anabi kankan ninu awon Anabi Olohun ti o gbe dide siwaju mi ayafi ki o ni awon omoleyin Alasunmo timotimo, ati awon ti yoo gba lati maa lo ilanan ijosin re fi josin, ti won yoo si maa tele ase re, leyinnaa awon arole buruku kan yoo tun wa, ti won yoo maa so nnkan ti won o le se, tiwon yoo si maa se ohunkan ti won o pawon lase re, eni ti o ba fowo re jawon logun, iru eni yi ni olugbagbo ododo tooto, eni ti o ba jawon lgoun pelu ahon re, iru eni yi ni Olugbagbo ododo, eni ti o ba jawon logun pelu okan re, iru eni yi ni Olugbagbo ododo, nkan to mo bii koro ni irugbin tokere ju, ninu igbagbo ko si mo leyin eleyi." (Muslim lo gba wa).

14.      Titele awon nkan ti mimo re pamon ti osi ruju ninu ofin esin. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

هُوَ الَّذِيَ أَنزَلَ عَلَيْكَ الْكِتَابَ مِنْهُ آيَاتٌ مُّحْكَمَاتٌ هُنَّ أُمُّ الْكِتَابِ وَأُخَرُ مُتَشَابِهَاتٌ فَأَمَّا الَّذِينَ في قُلُوبِهِمْ زَيْغٌ فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَابَهَ مِنْهُ ابْتِغَاء الْفِتْنَةِ وَابْتِغَاء تَأْوِيلِهِ وَمَا يَعْلَمُ تَأْوِيلَهُ إِلاَّ اللّهُ وَالرَّاسِخُونَ فِي الْعِلْمِ يَقُولُونَ آمَنَّا بِهِ كُلٌّ مِّنْ عِندِ رَبِّنَا وَمَا يَذَّكَّرُ إِلاَّ أُوْلُواْ الألْبَابِ {آل عمران/7}

“(OLohun) oun ni eniti ti o so Tira kale fun o. Awon aayah ti itumo won lo taara wa ninu re. Awon si ni ipile Tira. Awon miran si ni itumo won lopo mora won. ti awon ti gbigbunri kuro nibi ododo wa ninu okan won yoo maa tele eyi ti itumo won lopo mora won ninu re lati fi da rogbodiyan sile ati lati fi (tiran mo won) itumo re (to lopo mora won). Kosi si eni ti o mo itumo re afi Olohun. Awon agba ninu imo esin, won n so pe: A gbagbo lati odo Oluwa wa ni gbogbo re (ti sokale) ko si enikan ti n lo isiti ayafi awon onilaa kaye". (Suurah – al-imraan 7)

15.      Fifi owo yepere mu oro fi feran nnkan tolohun fe ati ituwo kuro nibi nnkan tolohun korira, ninife awon ota esin naa wa lara eleyi, tori pe ni nife si won maa ti eniyan lo sibi kikosewon ati jijowon, A gbawa lati odo Abbu Waaqid Allaythi ki Olohun bani yonu si, o so pe:

”Nigba ti ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) fee si ilu Mecca lati wo, o kowa losi agbegbe eti aaye kan ti n je Awwaazin (Aaye kan towa laarin Tohif ati Mekka) titi ti a fi de idi igi (Nabqi) awon keferi, igi yi je igi ti awon keferi maa n pejo sidi e, won o si maa pe ni agborandun fun gbogbonse, awa naa ba so pe: iwo Ojise Olohun se iru agborandun fun gbogbonse, awa naa ba so pe: Iwo Ojise Olohun, se iru agborandun fun gbogbonse fun wa gegebi awon naa se ni. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe: Olohun ma tobi o, Asa ni eleyi, eyi ti e wi yi naa dabi ohun ti awon omo (Israheel) isireli so fun Anabi Musa, tiwon ni seto Olohun kan fawon naa gegebi awon Olohun pupo se wa fun awon elebo Musa dahun pe: Alaimokan mo ni eyin eniyan yi o, leyinnaa Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) waa so pe: Eyin fee maa tele awon ilana ijosin awon asiwaju yin tii se (Yehuud ati Nasooroh) Juu ati omoleyin kirisiti." (Ibn Hibban lo gba wa)

16.      sise Igbiyanju lori ohun ti koleto lati segbiyanju le lori, ati fifun al quran ati hadeeth ni itumo ti kise tie, ati pe ninu ohun to leto titaniji si ni pe awon Hadith kan lupo mo Hadith to lalaafia, ti won je awon agbelero Hadith ti ko feserinle latodo Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba), awon naa ni awon Hadith ti won fi puro mo Anabi (ki ike ati ola Olohun ma ba), eleyi leto pe ki a sora fun – un gidigidi, ati pe a kogbodo fon iru Hadith bee kaakiri tabi ki a maa fi seri oro bakannaa tunni oro ri fun awon Hadith (Doif) to le, botile je pe die lara awon onimimo ri pe a le fi seri nibi awon ise asegbore ti ko je oranyan pelu majemu pe ko gbodo tako Hadith to lalaafia, sugbon nibi oro ise ijosin a ki i lo Hadith to le fi seri, Hadith ti a o maa lo nibi oro ijosin ni eyi ti o ba rinle pe o lalaafia latodeo Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba).

 

 

AWON MAJEMU TI O MAA JE KI ISE IJOSIN LALAAFIA LATI GBA WOLE

           

Dajudaju awon ise ijosin eru ko le tii di gbigba wole lodo Olohun ayafi igba ti awon majemu meji ba pe sibe.

Majemu Alakooko: sise ise ni tori Olohun nikan Olohun ti Ola re ga so pe:

وَمَا أُمِرُوا إِلاَّ لِيَعْبُدُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاء وَيُقِيمُوا الصَّلاَةَ وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ وَذَلِكَ دِينُ الْقَيِّمَةِ {البينة/5}

“A wa ko si pa won ni ase kan tayo pe ki won josin fun Allaahu (ki won je) oluse – afomo esin fun un, oni deede. Ki won kirun, ki won si yo Zakaah – iyen sin ni esin to yanju". (Suurah al-Bayyinah: 5)

Olohun ti mimo je ti e, ti Ola Re ga julo so bayi ninu (Hadith Qudsiy):

"Emi Olohun roro tayo awon ohun ti won n mu mo mi lorogun, eni ti o ba se ise kan, to tun ro nnkan miran po mo mi, maa pa oun ati ise re ti". (muslim:4/2289, hadeeth 2985)

Majemu Keji: Titele Rosuululahi (ki ike ati ola Olohun ma ba) lori ise ye, eyi ni ki ise ye je ohun ti o wa nibamu si ohun ti Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) muwa, bee si ni titele Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) ko tii lalaafia ayafi igba ti awon majemu mefa ti n bo wonyi ba pe:

Majemu Akoko (As – Sabab) okunfa: Itumo eyi ni pe ti eniyan ba sin Allaahu ti Ola Re ga pelu idi kan ti kosi ninu ofin esin, iru iye ni (Bid’ha) Adadasile kan ti won yoo da pada sodo eni ti o se e. apeere eyi ni: Awon eniyan kan ma n ji loru ojo ketadinlogbon osu Rojab pelu eri wipe oru yi je oru tiwon gbe Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) lo si oke sanmo, bee si ni ki a ji loru yan Nafila, Ijosin ni, sugbon nigba ti o ba papo mo iru idi yi, O ti di Adadasile, tori pe won ti mo iru ijosin bayi lori idi kan ti ko rinle ninu ofin esin. Tori pe oro pataki pupo ni ki ijosin papo mo idi ti ofin esin fi mule, eleyi si waa je ki opolopo Adadasile han nibi awon nnkan ti awon eniyan o maa lero pe Sunnah ni, to si je pe ko si ninu Sunnah.

Majemu keji (Al – Jins): Iru iran ise ti a se, kosi iyemeji nibi wi pe dandan ni ki ijosin papo mo ofin esin nibi iran iru ise ti a se. ti eniyan ba sin Olohun pelu ijsoin ti won o se iran iru re ni ofin ninu ofin esin iru ise bee koni je gbigba wole. Apeere eyi ni ki eniyan fi esin pa ileya, Ileya re koni alaafia tori pe o yapa si ofin esin nibi iran, tori pe a ki fi eran miran yato si, Rakunmi, Maalu ati Ag bo, Aguntan, tabi Ewure pa ileya.

Majemu Keta ni: (Al – Qodru) Iye onka: Ti eniyan ba gbero la ti salekun onka Rakat irun oranyan a o so pe Adadasile ni, ijosin ti Olohun kosi ni gba wole ni, nitori pe o yapa si ofin esin nibi onka, tabi ki a so pe nibi ondiwon. Ki alaye fi ye yekeyeke ti eniyan ba ki irun Zuhri ni Rak’at marun fun aperere, irun re yi ko lalaafia rara pelu apanupo awon onimimo.

Majemu Kerin ni: (Al – Kaaefiyyah) bi a ti se ise. Ti eniyan kan ba se aluwala ti o waa bere sise re pelu pe wiwe ese re mejeeji, leyinnaa oju re, a o so pe: Aluwala re yi ti baje nitori pe o yapa si ofin esin nibi ona ti o gba se e.

Majemu Karun ni: (Az – zaman) Igba tabi asiko ti a se ise: Ti eniyan kan ba pa eran ileya ni ojo akoko osu Dhul – Hijja won o ni gba wole gegebi ijosin eran ileya, nitori wipe o ti yapa si ofin esin nibi asiko.

Majemu Kefa: (Al – Makan) Aaye ti a ti se ise: Ti eniya kan ba se atipo (Itikaaf) ni aaye miran yato si Mosalasi, atipo re ko lalaafia, tori pe a ki i se atipo (Itikaaf) ni ibikankan ayafi inu Mosalasi.

 

 

EWU TO WA NINU ADADASILE

           

Aburu to wa ninu ninu Adadasile lagbara pupo, ewu to si wa nibe tobi pupo pelu. Idi ni pe o je ojuona kan ninu awon ojuona ti awon ota Islam maa n gba wole lati wo esin, nipa bayi ki onikaluku wa sora kuro nibi jije irinse ti won yoo fi wo esin yi, tabi je olukun lowo pelu owo, tabi iyi, tabi alasiri fun gbogbo Aladasile tabi Adadasile Agbelero tuntun ninu esin. Adadasile wa ninu awon ona ti awon ota Islam ati ota gbogbo Musulumi ti maa n lagbara lati pin isokan awa Musulumi yeleyele. Bakanna o tun je onan lati pin Igbiyanju won yeleyele, ati onan lati tu akojopo won ka. Ti Bidha ba wa han, to si fonka, ohun ti yi o koju ni wiwo Sunnah ati siso Sunnah di ole, eniyan o wa nile so ohun ti yi o sele nibi igbagbe, afoju kere awon ofin esin ipile, nipari pari, yi o ti eniyan lo si bi gbigbe esin re ju sile patapata , ki Olohun sowa kuro nibi iru aburu bayi. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Ijo mi yii maa pin si ijo aadorin ati die, eyi ti o lewu ju ninu won ni awon ijo ti yoo ma fi opolo ti won nikan se idajo esin, titi ti won yoo fi maa so ohun eto di eewo ti won yoo si maa so ohun eewo di eto." (Al-Mustadrak)

 O waa di eto fun enikookan wa pe ki o ma seri gbogbo nnkan taba fe se, toni ibasepo pelu oro ijosin sinu Tira Olohun Al – Qur’an ati Sunnah Ojise re (ki ike ati ola Olohun ma ba) ti o lalaafi, ati ilana ijosin awon Arole Afinimonan, tori pe eyi ti a ba se ni ibamu si tiwon ni won yoo gba wole lesin ti yoo si ba iyonu Olohun pade. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Mo ti fi nnkan meji sile si aarin yin, ti o se pe e ko le sonu mo laelae leyin mejeeji, awon nnkan meji yi ni. Tira Olohun ati Sunnah mi." (Al-Mustadrak 'ala As-sahihain)

Ohunkan ti o ba ti wa yapa si mejeeji, ohun ti o mu alaafia wa naa ni ki a gbe nnkan bee ju sile ki a si ri pe a ko pepe lo sibe rara, Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Iro pipa mo mi koda bii iro ti enikoo kan yin maa n pa mo ara won o, nipa bayi eni ti o ba moomo pa iro mo mi, ki iru eni bee yaa wa ibugbe re si inu inan." (Ahmad)

dajudaju Islam, Olohun ti gbe ofin kale fun, ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) si ti salaye re, gbogbo ohunkan ti Ojise Olohun ko ba salaye, ti kosi pepe le lori, kosi ninu esin Allaahu, nipa bayi eni ti o fe yege, ti o fee la, ti o si fee jere pelu ki o ri iyonu Olohun ati ife Olohun, ki o yaa ri pe awokose oun, ati eri oun ko je eyi ti o wa latodo Ojise ti a ti so kuro nibi asise tii se Muhammad (ki ike ati ola Olohun ma ba) tori pe ki ose imonan re ati ririn ni ojonan re nikan ni yoo muni ri iyonu Olohun ti yi o si gbe ni de Alujanna Re.

"قُلْ إِن كُنتُمْ تُحِبُّونَ اللّهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللّهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَاللّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ" {آل عمران/31}

“So pe: TI eyin ba ni ife Olohun e tele mi ki Olohun ni fee yin, ki o si fori ese yin jin yin. Olohun ni alaforijin, Alaanu.” (Suraah aali-imroon:31)

 Ki a ya gbe titele elomiran to yato si Ojise Olohun ju sile, tori pe awon eniyan yoku ki i se eni ti Allaahu so kuro nibi asise, asise yoo maa sele siwon, ife ojukokoro oro Aye ati titele ife – inu naa yio maa sele si won.

WIWA ISORA FUN ALADADASILE ATI ILERI IYA TO WA FUN

 

Abdu Allah Omo Daelamiy so pe:

”O deti gbo mi pe Akoko ohun ti yio mu esin kuro nile ni gbigbe Sunnah ju sile, esin yoo maa lo pelu ki Sunnah kookan maa lo, gegebi agbara okun se maa lo diedie diedie."(Sunan Ad-Daarimi).

O wa di eto fun enikookan wa lati gba, Sunnah Rosullahi (ki ike ati ola Olohun ma ba) to lalaafia mu daradara, bakanaa ipepe to je ti ododo lori sise amulo Sunnah di eto, tori pe gbogbo oore wa nibi tito ipase Ojise Olohun ati di diro mo Sunnah re (ki ike ati ola Olohun ma ba), yala nibi ise, tabi loro enu, Bakanna o ti di oranyan fun wa ki a gbe eyikeyi ilanan Adadasile to yato si Sunnah ju sile, gegebi ose je dandan fun enikookan wa ti o ba ri tabi ti o ba gbo ohun ti o yapa si ofin esin Olohun tabi o ri ohun ti kosi ninu ofin esin Olohun ki o si maa se isiti ki o si maa salaye ododo, ki a le baa gbaa wipe o n daabo bo esin Olohun, o si n gbe Asia Islam ga. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”E mu oro Olohun de etigbo awon eniyan, ko da biko ju Ayat kan pere lo." (Al-Bukhari).

ki a kora duro niwaju awon Adadasile, ati ki a maa pepe lo sibi ayipada re, won ko foju fo fun eni kankan wa, nibamu bi agbara wa ba se to naa la o ma sayipada ibaje. Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Enikeni tobari ohun ti koda, ki o se ayipada re pelu owo re, ti ko ba lagbara eyi, ki o lo ahon re, bi ko ba lagbara eyi, ki o lo okan re, eyi si ni igbagbo ti o le julo." (Muslim).

ki o ri pe ipepe oun yi, ati ilanan ti oun maa lo fun ayipada ati alaye ti o fee se wa nibamu si ohun ti Allaahu pase re pelu gbolohun Re yii:

ادْعُ إِلِى سَبِيلِ رَبِّكَ بِالْحِكْمَةِ وَالْمَوْعِظَةِ الْحَسَنَةِ وَجَادِلْهُم بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ {النحل/125}

“Pe ipe si (inu – islaam) oju ona oluwa re, pelu ogbon ijinle ati isiti to dara,kio bawan jiyan lonan tio dara ju,Olohun re lomon awon to sonu kuro ni ojuonan re, osi mon awon eni imonan” (Suurah – a – n Nahl 125)

Dajudaju ao gbodo gba awon oro esin wole lati odo gbogbo eni ti npe apemora imo ati agboye, sugbon o je dandan ki a gba wole latodo awon ti a le gbara lewon ninu esin won, imo won, Asaje won, Iberu Olohun won ati ifokantan won, Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Awon onimimo ni awon Arole awon Anabi Olohun, Awon Anabi Olohun kosi fi ogun owo Dinar tabi Dirham kankan sile bikosepe imo ni ogun ti won fi sile, eniti o ba di eleyi mu, o ti ri ere topo dimu.” Add Ibn Hibban

Ki a maa je ki awon afojusun wa ni gbogbo igba maa je erenje iru eyi ti Ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Eni ti o ba pepe lo sibi imonan yoo gba esan iru awon esan ti eni toba tele yoo gba, eleyi ti nkankan kosi ni dinku ninu esan awon to tele imona naa, bakannaa eniti o ba pepe lo sibi anu, yoo ru iru eru ese ti gbogbo awon toba tele maa ru, ti nkankan kosi ni dinku nibi eru ese awon to tele won.” (soheeh muslim:4/2060, hadeeth 2674)

Awon adadasile si wa ninu anu.

Ni idakeji, eni ti o ba fese eniyan le onan aburu – (Adadasile si wa ninu aburu) – eru ese aburu yio wa lori eni to se e, bakannaa, ese eni ti o ba tele naa yio tun wa lorii re. Ojise Olohun ((ki ike ati ola Olohun ma ba) so pe:

”Oro to je ododo ju lo ni Tira Olohun, Imona todara ju si ni imona Muhammad, oro to si buruku ju ni Agbelero, gbogbo Agbelero ni Adadasile, gbogbo Adadsile si je anu, gbogbo anu si n gbeniyan lo sinu inan.” (Sahih Ibn Khuzaimah).

Nipa bayi titobi Ewu Adadasile ninu esin Olohun waa han kedere, o waa di dandan fun gbogbo eni ti o ba fe se ise kan, tabi o fee pase ise kan ni sise ki o koko woye si i boya o ba ofin esin Allaahu mu abi kobamu, ti o ba ba ofin Allaahu mu, yoo se yoo si pa awon eniyan ni ase sise re, bakan naa yoo se won lojukokoro sibi sise re, yoo si gbiyanju lati mulo, kofi le leto si ohun ti Ojise Olohun (((ki ike ati ola Olohun ma ba)) se ladehun fun – un. Sugbon ti o ba je ohun ti o yapa si ofin esin Olohun ((ki ike ati ola Olohun ma ba) kose, bakannaa, ti awon Arole Afinimona kose, o gbodo gbe jusile ni, ki o si ri pe o wa isora fun awon eniyan nibe, Iyen tumo si iberu wi pe ki o ma lo jepe ese ori ise yen yoo wa lorii re, bakanna ki won o maa tun di eru ese gbogbo eniti o ba n se titi di ojo Igbende le lori, oro yi lewu pupo, o se dandan ki a taji nipa re, ki a si wasora fun gidigidi.

 

WWW.ISLAMLAND.COM