IPÓ OBIRIN NINU ISLAM

IPÓ OBIRIN NINU ISLAM

IPÓ OBIRIN NINU ISLAM
المرأة في ظلال الإسلام بلغة اليوروبا

 

Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 

Itumo ni ede Yoruba
European Islamic Research Center (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Ridwan Allah Murtadho
Atunto
Abd Ar-Razzaq Isa
 

www.islamland.com

 

بسم الله الرحمن الرحيم
Ni Orukọ Ọlọhun Ọba Àjọké́́́-aiye Ọba Asakẹ-ọrun
A dupe fun Olohun, a toro ike ati ige fun Annabi wa Muhammad ati awon ara-ile re ati awon ti won ba lo’gba pata, leyin na:
Olohun to ga julo so bai pe:
Itumo: (Enyin enia, dajudaju A da yin lati ara okunrin ati obirin, A si se yin ni ijo nijo ati iran-iran ki e le baa moo mo ara yin. Dajudaju eni ti o ni ola ju lodo Olohun ninu yin ni eni ti o paiya (Re) ju.) Suratu Hujuroot 13.
Ninu asise to buru ju ni ki won se afiti si ara islam ohun ti ko si ni ara re, ninu re ni oro ti won sope Islaamu o fun obirin ni aponle, owo ati eto re, Olohun nso ninu Al’quran bai pe:
Itumo: (Bi e ba korira won, osese ki ekorira nkankan ki Olohun osi fi oloopolopo rere sinu re.) Suratu an-nisaai 19. Olohun tun so bai pe:
Itumo: (Atipe ninu awon ami Re (Olohun) ni dada awon aya fun yin lati ara yin ki e le ba ma ri ifaiyabale lodo won, O si se ife ati ike si arin yin. Dajudaju awon amin mbe ninu eyi fun awon enia ti o nronu.) Suratu Ar-ruum 21.
Nipaapa ni ogbajumo ipepe fun awon eto, ominira fun awon Obirin, ati bibere sise dede pelu won pelu Okunrin. o sese ki awon ipepe ati ibere won yii je ohun atewogba ni awon awujo ti ko si aponle ati owo kankan fun obirin nibe, ti osi fun ni eto Kankan. Sugbon iru ipepe won yii je ohun kayefi ni awujo esin Islam eyiti o fun Obirin ni eto, aponle ati owo saaju koto bere fun, ti osi se awon aponle won yii ni ofin dandangbon ti kosi ona abayo lati gun ri kuro nibe. Beeni, o seese ki a ri eniti yio ma se aburu si obirin ti yio si ma ko eto re fun, okunfa eleyi ni igbeju sile awon eko esin Islam ati awon itosona re!!
Dajudaju awon olupepe fun ominira ati eto Obirin – gege bi won ti se nlero – awon ibere won yi ko jo si ibi awon irori meta wonyi:
1). Ibere fun ominira awon obirin.
2). Sise deede awon obirin pelu awon okunrin.
3). Ibere fun eto awon obirin.


IBERE FUN OMINIRA AWON OBIRIN:

Dajudaju gbolohun ominira ntoka si nkankan ti won fi oude de, ti oni bukata si ki ase inana re, gbolohun naa asise to po nbe nibe, toripe yio mo gbin sinu okan pe eru ni obirin je ti o si soranyan ki a tu kuro loko eru. Dajudaju ominira pelu agboye re ni sanpona nkankan ni ti ko le sele toripe omo-enia pelu adamo re je eniti won fi ounde de ni, ti ikapa ati agbara re ni aala, atipe omo-enia ni awujo won, yala ni awon awujo ti asiko yii tabi awujo toti re koja won yio mo semi labe boji awon eto ati awon ofin eyiti yoo mo dari alamori isemi won, won yio si mo s’eto awon isesi isemi won pelu re. Nje eleyi tumo si pe won kii se olominira bii ? Tobawaribee, a je pe ominira ni aala, ti o ba ti rekoja re yio bo si ipo awon eranko ti kosi ofin abi ilana kankan ti ndari won. Ojogbon “Ph.D Henry Makow” (okunrin onimo-ijinle omo amerika olusewadi eni-esa nibi awon isesi ati awon alamori nipa awon obirin lagbaiye) sope: Dajudaju siso awon obirin di ominira ara won itanje kan ni ninu awon etan awon ofin agbaiye to je tuntun, ete kan to lagbara ni, to so awon obirin amerika nu to si pa awon olaju iwo-oorun s’ofo”.
Ododo oro nipe dajudaju islam ni esin akoko ti o ta awon obirin lore ibasepo ati ilopo pelu awujo leyin igba ti ajose won pelu awujo mbe ni ohun ti ko le sele ayafi pelu alagata aayo kan tabi alamojuto re. Dajudaju Islam ko ko fun obirin ayafi nibi ominira to le mu u kojaala, ti yio siso di alaini itiju. Irufe awon ominira bayi won se leewo fun awon okunrin na ni bakan-n-kan na, dajudaju agboye ominira ninu Islam ni oro ojise Olohun - ki ike ati ola Olohun maa ba –to lo bayi: (Apejuwe eni ti nso aala Olohun ati eni toko sinu re da gege bi apejuwe awon ijo kan ti won ngbero lati yo ipin ti kaluku fun ninu okooju-omi, abala isale wa bo si owo awon kan ti abala oke si bo si owo awon apakan won, awon to wa ni apaasale wa nbe ni eniti ba nrakan si omi won yio lo ba awon ti won wa loke, won wa sope: ti a ba si le fo die ninu ipin wa ninu (oko oju-omi) yi ko ba dara o, ti a ko ni fi ma ko inira ba awon ti won wa loke wa, ti awon ti won wa loke ba fi won sile pelu erongba won yi won yio jo pare papo ni, a mo ti won ba dawon lowo ko won yio la, won yio si jo la lapapo). Sohihu bukhari, idi 2 ojuewe 882.
Eleyi ni agboye ominira ninu islam, ki lilo-bibo enikookan o ni itumo pelu awon alana ofin sharia ti yio ma so ki inira mo kan emi enikankan ati awujo re.
Dajudaju ohun to l’eto t’oye ki awon olupepe fun ominira awon obirin o ma bere fun ni; eyikeyi awon ofin to ba dara ju, to sanfani ju to si je iso ju fun aponle awon obirin ati aabo fun awujo. Nje eto ati ofin Islam eyiti o ka obirin gegebi omaya ati olupe fun okunrin loda losi loore abi awon ofin agbelero agbaye eyi ti won ngbero lati so obirin di alaini tiju, ti yoo si jee eni etoo fun gbogbo enia lati ba awujo je?

SISE-DEEDE AWON OBIRIN PELU AWON OKUNRIN
Dajudaju bibere ibadogba awon obirin pelu awon okunrin ni bibadogba ti o pe nibi gbogbo nkan ohun ti ko le seese ni nitori yiyato adamo enikookan ninu awon okunrin ati awon obirin, yala ni agbegbe ara ni tabi nibi lakai tabi nibi emi, nigbati deede larin eya kan – eya ako tabi eya abo – baje alaamori kan ti ko le sele latara awon iyato to nbe laarin won, ninu eyi ti fi nleto ju nipe ki ai rorun ibadogba to gbopon ju wa nigbati eya ba yato si ara won, Olohun ti ola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (Atipe gbogbo nkan ni A da ni meji-meji ki e le baaje eniti yio mo ranti.) suratu Ad-dhariyat 49
Eleyi nipe dajudaju Olohun oba, afomo Re Oba tola re ga ju nigba to sẹda awon abara meji O da eni kookan lori adamo re ti o si yato si ti elomiran, bakanna ni ikookan je pipe fun ekeji ni asiko kan naa. Ti a ba woye si eya kan a o ri pe o pin si iran meji, o si soranyan ki a so pe ko pin si iran meji ayafi nitori ojuse-pataki meji, to ntunmo si pe ti ojuse-pataki na ba lo je eyokan-soso eya na ba ma je eyokan-soso lori re, ko si nii pin si iran meji, a mo pinpin re si iran meji ntoka si pe gbogbo iran kookan ni o ni adayanri ti e nibi bibe re sugbon eya dawon papo. Apejuwe eleyi ni oru ati osan won da gege bi iran meji fun eya kan ti i se igba, iran yi ntoka si pe yio ma be fun oru ojuse pataki kan ti i se ifarasin, atipe yio ma be fun osan na ojuse pataki kan ti i se lilo-bibo ati igbiyanju, okunrin ati obirin pelu aworan yi won je iran meji fun eya kan ti se omo-enia awon nkan-kan wa nbe ti won yio ma bere lowo okookan won pelu iroyin jije enia re, leyin na awon nkan ti won yio ma bere lowo okunrin nikan wa ti won yio si ma bere awon ohun miran lowo obirin nikan leyi to jepe o rorun fun wa lati so pe: Iran-meji lati ara eya kan, awon ojuse-pataki ajokopa kan nbe fun won gege bi eya kan-soso, ati awon ojuse-pataki to da yato wa fun ikookan gege bi iran meji lati ara eya kan).
Yio wa foju han gbangba nibi nto ti siwaju aile-sele bibara eni-dogba larin awon mejeeji nibi gbogbo nkan, atipe sise isise lori eleyi je iwa toburu jai, nitoripe o je isise lati s’ayipada adamo ati ohun ti won sé’da omo-enia le lori, bakanna lotunje isise lati yepere obirin ati lati dóju ti nitori ohun to só po mo o nibi jijade re kuro nibi adamo ti Olohun da mo ati eleyi ti yio ma je iyori aburu fun awujo.

IBERE FUN ETO AWON OBIRIN
Ko si ofin kan tabi eto kan yala lateyin wa ni tabi nisin yi ti o so awon iwo obirin ti o si gbe ipo won ga gege bi Islam se so o. Lati igba ti imole islam ti yo pelu gbigbe ojise nla muhammadu – ki ike ati ola Olohun lo ma ba – dide eleyi ti o je ohun tuntun ninu emi awon musulumi awon ti won igbagbo pelu re ati pelu jije alagata won ni awujo omo-enia, o je isele ti o seni l’eemo ju ninu itan omo-enia, isele yi je kayefi nibi gbogbo nkan nibi yiyara tan-ka re ati kikari re ati sisunmo re si agboye ati didunimo re mo adamo omo-enia kosi iruju ati adapo nibe kosi si iforiso adamo omo-enia to dara nibe, ki a mu ninu otun yi ninu ohun ti Islam mu wa ninu ayipada nibi wiwoye si agbekale obirin ati awon eto re ohun ni nkan ti o jewalogun nibi iwadi yi, eni ti o ni tira “Hadoorotu-l-Arob” (olaju awon larubawa) so pe: “Iyi islam lori awon obinrin kopin si bi gbegbe iyi ati ola fun Obinrin, sugbon oje esin akako to se eleyi fun obinrin.”
O tun so ni aaye miran ninu tira na ni oju-ewe (497) pe: “Awon iwo loko-laya ti al-Qur’an s’alaye ati eyi ti awon onimo taf’siri so lola ju opolopo awon iwo loko-laya ti awon geesi lo.”
Dajudaju awon iwo obinrin o leto ki won bere fun ni awon awujo ti ko fun ni awon eto re, tabi ni awon awujo to je pe o fun ni awon eto sugbon ti ko awon ofin de, latara be o so di eni iyepere ati ibaje, ti o waa di nkan isere, ati ohun ti won yio fi ma gbo bukata, ati ohun igbadun. Sugbon islam jé onideede si obirin ju....o si so awon eto re, o si fun ni awon eto ajoni ni awujo ati awon eto-adani lati se isemi ti o dara ti o ni alaafia ti yio si le ma se ojuse re ti Olohun ‘da nitori re.


IPO OBINRIN NI AWON ASIKO TOTI RE KOJA

Ipó obinrin ni awujo ígbá aimokan:
Ni paapa, obinrin be ni awujo igba aimokan ki islam to foju han ni ohun iyepere, eni abosi, ti won mo nje awon eto re, ti won si ma gba awon dukia re, won si mo nkaa si ohun ti ko ni itumo, ko le je ogún nitori pe won kii fun eni ti ko ba le gun esin lo si oju-ogun ni ogún je ti kosi le ko oro-ogun wa’le, bi kii se pe won mo nje (obinrin) m’ogún ni leyin ipakoda bale re gegebi won ti mo jogun dukia, to ba nbe fun oko re awon omo okunrin lati ara iyawo miran, eyi ti o dagba ju ninu awon omo won yii leto si iyawo baba re kekere ju elomiran lo, yio jogun re gegebi won ti njogun dukia, ko ni kuro ninu ile re titi yi fi san owó emi ara re, won yio si ko fun lati pada si inu ile oko re leyin igba ti o ba ti ko sile tan, okunrin na le fe eyi to ba wu le ninu awon obinrin lai fi aala si, kosi eto kankan fun lati sesa oko, kosi si fun ninu awon eto kankan lori oko re, kosi si ofin kankan to ko abosi okunrin si iyawo re. Awon larubawa nbe ni igba aimokan ni eniti ki fe omo obinrin, won kaa obinrin si ohun nbu ati adanwo, nigba ti won ba bi omo-obinrin fun okan ninu won ibanuje ati ogbe-okan yio de ba. Ikorira omo-obinrin lodo won de gongori pipa, papaa pipa won ti di ifisise-se lodo apakan awon idile larubawa, botilejepe okunfa pipaa yii amo yato lodo apakan won si ekeji pelu yiyato ipo idile kookan ni awujo, o nbe ninu won idile to mo paa omo-obinrin niti pipaya iyepere re, o si mbe ninu won eni ti ma npaa obinrin nitori aleebu adamo re (bi aisan), Olohun tola Re nso bai ni eni ti n se iroyin ipo won nibi isesi won yi:
Itumo: (Atipe nigbati won ba fun enikan won niro adunnu (bibi) omobinrin, oju re yio yi pada si dudu ti yio si mo banuje * Yio ma fi ara pamo fun awon enia nitori ohun ti won fun u niro re, Yio wa moo lero pe abi ki omu dani pelu abuku ni abi ki o ri molé (laaye) ? E gbo o, ohun ti nwon da lejo ma buru.) Suratu An-nahli 58-59.
O tun nbe ninu won eniti ma npa awon omo re niti pipaya osi awon ye ni awon alaini ninu awon larubawa, Alqur’an ti se akosile eleyi ninu oro Olohun tola re ga ju to so bai pe:
Itumo: (Atipe ese ma pa awon omo yin mo nitori ipaiya osi, Awa ni anse ije-mu won ati fun eyin na. Dajudaju pipa ti e npa won je ese ti o tobi.) suratu Al-isroohi 31.
Obinrin je eni ti ko le gbadun awon eto re to je ti adamo, o nbe ninu awon ohun-jije eyi ti won se adayanri re fun awon okunrin ti won si se ni eewo fun awon obinrin, Olohun tola re ga ju so bai pe:
Itumo: (won tun so wipe: Ohun ti nbe ninu ikun awon eran wonyi je ti awon okunrin wa nikansoso, osi je eewo fun awon obinrin wa.) suratu Al’anhaam 139.
Ko si nkankan fun lati seyanran ju amojuto okunrin fun lo ati olugbeja fun u nibi ohun to ba fe yepere aponle re ati didaabo bo iyi re.

Ipó obinrin ni awujó awon awon ara India ijohun
O wa lati inu iwe “al’faydia” okan ninu awon iwe mimo eleyi ti o ko awon ipile ti esin “Al’barohimiyyah” si inu nipa ohun to nii se pelu obinrin, eyi ti olo bayi:
“Ofin “Al’barohimiyyah” se opinya laarin okunrin ati obinrin nibi pataki omo-enia ati nibi awon eto miran, o ja obinrin kuro nibi eto jije olominira o wa fi si abe gaba okunrin nibi gbogbo alamori isemi re gegebi ose fi n rinle wipe ko leto fun obinrin nibi eyikeyi ipele ninu awon ipele isemi re wipe ko da nkankan se nibamu si fife re, koda ki alamori na je okan ninu awon alamori inu-ile re, yoo mo be labe itoju baba re nigba kekere, nigbati oba di omoge yio wa labe oko re, nigbati oko re ba si pakoda sise amojuto re yio pada si odo awon omo iya baba re, ti ko ba ni awon wonyi yio seri pada si odo alase-ilu (tabi adajo), ko si fun obinrin nibi eyikeyi ipele ninu awon ipele isemi re eto kan si ominira tabi lati da duro tabi lati se ohun towu nibi ohun to ba nfe.).
Ipo obirin ni awujo awon “india” o da gege bi ipo awon erubinrin nibi titele oko re ti ko si erongba kankan fun, ko le da se nkankan ninu alamori re).
Ko le ni oko miran leyin iku oko re, koni eto lati mo semi leyin iku re, bi kii se pe ki o ku ni ojo ti oko re ba ku, won yio dana sun po mo ni ori adogan kan na. Iwe esin won so bai pe:
“O dara fun obinrin ko finu-findo bo si inu igi-isepe ti won ti palese le lati fi dana sun oko re toti ku, won je eni to je pe ti won ba ti gbe oku na si ori igi-isepe iyawo re yio bo sibe leni ti yio ti wo aso kan ti yio bo oju re, baba-oloosa won yio wa bo aso oju re, yio si bo egba-orun re ati awon nkan osó re yio si pin fun awon alasunmo re leyin na won yio gba awon nkan keekeke owo re, agba-awo yio wa gba owo-otun re mu, yio wa mu yipo igi-isepe na ni eemeta, leyin na won yio ti sinu igi-isepe na, won yio wa gbe oko re si iwaju re lerogba pe eleyi ntoka si iteriba re fun oko re, yio wa yiju si yio si joko si igberi re l’eni ti yio gbe owo-otun le e, won yio wa sona si won yio si jo nina pelu oku oko re, lerogba pe eleyi ni yio jogun idekun fun, ti yio si ma be pelu re loke sanmmo fun odun marundinlogoji egberun l’ona egberun (35,000,000)..., atipe pelu jijo nina yi yoo fi se afomo fun awon araale iya re, araale baba re ati araale oko re, won yio si fi fo oko re mo nibi gbogbo ese....won yoo si kaa si eyi to mo ju ninu awon obinrin ati eyi ti o biyi ju ni oruko ati eyi todara ju ni iranti laarin awon enia, isesi yi ti wa fonka laarin won niti fifanka ti o lagbara gan leyi ti o jepe won dana sun egberun mefa (6,000) omobinrin larin odun mewa larin odun 1815 si odun 1825, sisise to ofin yi si lobe titi di ipari ogorun-odun- ketadinlogun ti won fagile isesi yi latara ikorira awon opo esin “al’hanuud”).
Ninu ohun ti ntoka si ipo tole koko ti obinrin ile India ti n semi ni asiko ye ni ohun to wa ninu awon ofin “hindusi” l’aye ti n so bai pe:
“kosi ohun to buru ninu ibudesi eyiti won pebubu re, abi afefe, abi iku, abi ina-jehimi, abi iwo, abi ejo-oka, abi ina to buru julo bi obinrin”.
“O ma be fun obinrin ni awon igba miran opolopo oko, ti isesi re yio wa da bi ti oni nanbi ni bakan-n-kanna”.

Ipó obinrin ni awujo awon saina (china) ijohun
Obinrin nbe ni awujo awon saina johun gege bi eni ti o ni iwe “itan olaju” ti sope "obinrin je olutele fun okunrin ti yio lo gbogbo isemi re sibi titele boti je wipe o je eniti won ko fun nibi gbogbo eto re to jemo dukia ati ajose pelu awujo, o je eni ti won fun ni aala ti koni ikapa lori alamori ara re kankan bi kii se pe okunrin ni alamojuto re nibi gbogbo re bo ti je pe ko leto si eko kiko ati olaju, oranyan ni fun lati deju monle yio ma se bo i sin oko re, yio si ko nipa aso riran ati awon okunfa iseranlowo lorisirisi, o si gbodo ge irun ori re to ba ti pe omo odun meedogun, o si gbodo loko to ba ti pe omo ogun odun baba re ni yio si yan oko fun pelu iranwo alagata.
Bibi re (obinrin) won mo nka si ohun aburu, (W. Durant) so ninu iwe re “itan olaju” pe: “Dajudaju awon baba won a mo bere ninu adua won pe ki won o ro awon loro omo-okunrin. Ninu awon okunfa nla iyepere fun awon iya ni opolopo igba ni ki won o ma ni awon omo okunrin, toripe awon ye ni agbara ju awon omobinrin lo lori ise-oko sise, won ni agbara lati joju ogun jija. Won ka omobinrin si aleebu fun awon baba won, toripe won yio ma re won ti won yio si ma se suru lori rire won leyin na ni won yio sin won lo sile oko won...titi ti isesi pipa awon omobirin fi foju han. Ti won bi omobirin sinu molebi kan to wa po koja bukata won, to wa se dede igba ti awon molebi na nkoju isoro lati na’wo le won lori won yio gbe won ju sinu igbo ni titi ti iri-oru yio fi pa tabi awon eranko abija ti awon enia yoku ninu molebi ko si ni mo nkankan nipaohun ti won se pamo. Ówe saina (chaina) to tipe a ma so bai pe “mo teti gbo oro iyawo re daada, sugbon mo gba ni olododo”.

Ipó obirin ni awujo awon “Romania” ijohun
Eni ti o ni tira “Itan olaju” nso bai pe, “Bibi obinrin je ohun ti won ki rankan re leyi ti nbe ninu awon isesi to gbajumo, isesi se leto fun baba nigbati won ba bi omo-ikoko tabi omobinrin fun pe ki o pese re fun pipa, a mo nidakeji won je eni ti rirankan won le gan nibi ki won ni awon omokunrin”.
Papa omobinrin ni awujo awon Romania je ohun ti won fi onde de ti ko nikapa kankan lori alamori re, okunrin ni yio ma doju re ko ibi ti o ba fe, gbogbo sise re ati ikapa re owo okurin nikan lowa, o ni awon iwo tope lori gbogbo enia kookan ti nbe ninu idile re, o si nbe ni abe awon ojuse re wipe oni kapa ko se idajo lori iyawo re lati gba emi re ni awon abala ikefin kan”. O si tu lagbara lori awon iyawo awon omo re ati awon omo-omo re, ti agbara yi si rokirika tita-rira, ibawi, ilenijade ati pipa.
Atipe obinrin ojuse nipe ko gbo ko tele ko si se, ko leto lati yi ohun pada tabi lati bere, ogun-jije eewo ni fun nigbati o je pe gbogbo ogun omokunrin agba ni won yio ko fun, alamori na si ba won debi pe okunrin ni eto lati da eni ti kii se ara molebi won po mo molebi won, o si le mu eni to ba wu kuro ninu ebi pelu ona tita-rira.

Ipó obinrin ni awujo awon “Yunaani” (Jew) ijohun
Ipin obinrin ni awujo awon Yunaani ko dara ju ipin re lodo awon ijo to ti saaju, iyepere na debi pe o fi di ohun ti won ngba gege bi nkan yiya, “Tarylong” so bai pe: “Obinrin ti o ba mo omo bi daada o je ohun ti won ma nya lodo oko re lati bi awon omokunrin fun ilu latara okunrim miran.
O je eni ti won se olaju leewo fun, iyepere na de ipo ti won fi nso gbolohun pe:(egbin ni latara ise esu) si.
Ko si ofin kankan ti yio daabo bo, ogun jije je ewo fun, ko ni ikapa lati se nkan towu pelu dukia re, won kodi ominira re ati erongba re, yio ma teriba ni gbogbo isemi re ni abe ikapa okunrin ni, ko ni eto kankan lati bere fun itusile nigbati o je pe eto pombele lo je fun okunrin....
Debi pe alamori na lodo won de aala pe awon ti won npe ni onilakai inu won nso pe: O soranyan ki won o mo si n oruko obirin mo’le bi won ti ma nsin ara re mo’le...
Obinrin lodo awon “yunaani” ko je nkankan ayafi eni ti mbe ni ipo isale(iyepere). Eni to ni tira “olaju awon larubawa” so bai pe: “Awon “Giriiki” ni apapo- je eni ti won ma nka awon obinrin si eda yepere eleyi ti kii sanfani ju ki piposi o ma be lo ati siseto ile, nigbati obirin ba bi omokunrin kan ti kope l’eda won yio pa obinrin na.
Nipaapa sorosoro won to gbajumo “Damostine” o ti yaworan ipo obirin pelu oro re to so pe: “Awa ma nmu awon obirin alagbere fun igabdun, a ma nmu awon aayo lobirin ni akolekan lati mu ara wa ji pepe lojoojumo, a si ma nmu awon iyawo lati je ki won o bimo fun wa lona ti o bofin mu”. Ewo wa ni ipin obirin ninu awujo yi, eleyi ti awon ololaju be so oro yi nipa re?!

Ipó obinrin ni awujo awon “Yehudi” ijohun:
Obinrin je orisun aburu ati ipile re lodo won gege boti se wa ninu oro “At-taorata”: “Obirin ni ipile aburu pelu okunfa re ni opolopo fi sonu”.
Ipó obirin ni awujo awon yehudi kosi laaye to dara rara, papaa won ti gbe awon ofin won kale nipa isesi re won wa ni isora nibe gege bi won ti se iroyin re ninu “sifari aljamia’” (tira akojo):
“o yimi po ati okan mi ki nle ba moo, ki nle moo semi, ki nle moo wa ogbon ati oye, ki nle ba mo pe aburu aimokan ni, ago iwa were ni, mo wa ri pe won fi ase si kiku obirin eleyi to je pe ohun ni ferese ti okan re si je oju-ona awon owo re mejeeji si je awon onde to dara niwaju Olohun ko le la kuro nibe sugbon alasise won yio gba mu”.
O nbe fun baba ikapa pombele lori molebi re papa-julo awon obirin yio fe won fun awon ti o ba wu, yio si fi won toro fun awon ti o ba wu, o si le ta won to ba wu bo ti se wá ninu tira “sifaru alkuruji” ni ori kokanlelogun ese eleekeje si ese ikokanla.
Oni iwe “itan olaju” so bai pe:” o mbe fun baba lori awon molebi re ola ti o fe, ile je nkan-ini re ko si aaye fun awon omo re lati moo be lori isemi ayafi ti won ba ntele ase re, ohun ni orileede won, o mbe ninu ikapa re ti o ba je pe olosi ni ki o ta omo re obinrin ko to di omoge. Bakanna ni o tun ni eto sanponna lati fe fun eni ti o ba wu, botile jepe ni awon apakan igba o le gbe apakan eto re sile ti yio si toro lowo re pe ki oyonu si sise iyawo.
Nigbati omobirin yehudi ba ti loko ije-aayo lori re yio kuro lodo baba re lo si odo oko re yio wa di ohun ti won yio ka mo okan ninu awon dukia re gege bi ile, erukunrin, erubirin ati owo, eleyi ohun ti awon oro AT-taorata da le lori ninu “sifaril’kuruji” ori ogun ese eleeketadinlogun.
Lafikun eleyi, awon ofin yehudi ti ko fun omobirin nibi awon nkan ti baba re ba fi sile nigbati baba re ba ti ni awon omo okunrin gege bi o ti wa ninu “sifir –l-Adad” ni ori iketadinlogbon ese eleekejo: “Eyikeyi okunrin ti o ba ku ti kosi ni omo okunrin won yio dari dukia re si odo omo re obinrin”.
Awon iyawo lodo won nigba ti oko re ba ti ku ni yio ti d’ari laidonna-penu lo sodo aburo oko re, inu re (iyawo) dun si o tabi ko dun si ayafi ti (aburo oko re) ba yowo kuro loro re lo ku, gege bi o ti wa ninu iwe mimo “mojemu lailai”:
“Ti awon omo-iya kan ba ngbe papo ti okan wa ku ninu won ti ko si ni omo okunrin, iyawo eni ti o ku ko ni bo sita lo sodo okunrin alagata, omo’ya oko re ni yio wo’le ti, ti yio si so di iyawo re yio si ma pe awon oranyan omo’ya oko fun u”
Bakanna nipe won kii jeun tabi mu omi papo tabi sun po pelu obirin ti o ba nse nkan-osu, won yio jinna si titi yio fi mora, awon ofin won so nipa isesi yi,
“Dajudaju obirin kii se eni-mimo lati ojo ti o ba ti bere si ni furamo pe nkan osu re ti sunmo koda ko ma si oripa kan ti o han, o ti di dandan fun oko re ki o ma f’owo kan koda eyi to kere ju ninu ika-owo, won ko yonda fun lati fun u ni nkankan koda ko je ohun ti o jina si, ko gbodo gba nkan lowo re ko si gbodo ju nkan si tabi ni idakeji won ko yonda fun u bakanna, won ko yonda fun lati jeun pelu re lori tabili kan na ayafi ti nkan ba la abo laarin won, won ko yonda fun lati mu omi ti o ba mu seku ninu ife, won ko si yonda fun awon mejeeji lati sun papo lori ibusun kanna won ko gbodo gun keeke kan na papo tabi esin kan na, ti won ba nsise papo ni aaye kanna pelu mojemu pe won ko gbodo fi owo kan ara won, ti oko re ba nsaisan ti kosi si eni ti o le duro ti ju ohun na lo won yonda iye fun ni okuru-gba ti ko ba ti ni fi owo kan ni ifowokan igbadun, a mo ti o ba jepe obinrin lo n sa aisan won ko yonda fun oko re lati duro ti koda ko je pe ko ni fi owo kan, obinrin ti o ba sese bi’mo alaimora ni, iye nipe ti o ba bi omo okunrin yio ma wa be fun ojo-meje, ti o ba bi omo obirin yio wa ni alaimora fun ojo merinla, ko ni we ayafi leyin ogoji ojo ti o bi’mo okunrin, tabi leyin aadorin ojo to bi’mo obirin”.

Ipó obirin ni awujo awon “Kiristaniti” ijohun
Papaa awon baba ile-ijosin “soosi” ti re koja aala ni awon asiko ti nbe ni arin meji ni ti kikoja aala nigbati won ka obinrin si ipile aburu ati orisun ese ati ibere adanwo eleyi to de ba awon omo-enia pata, nitori eleyi ni ajosepo larin okunrin ati obirnin fi je egbin to soranyan ki o jina si koda koje latibi ipase igbeyawo tabi yigi siso leyi ti o ba ofin mu, “Al-Qodis Tertullian” nso bai pe: “Ohun (obinrin) ni abawole esu sinu emi omo-enia ohun na ni o ti omo-enia lo sibi igi ti won sebi le, olutako ofin Olohun oluba-aworan ti Olohun ya je – ti i se okunrin -.
Iwe “Ad-danmorky” (Wieth Knudesen) ti s’alaye ipo obinrin ni awon asiko arin-gbungbun o so pe: “Akolekan pelu re kere gan lati afi tele adojuko ojuona awon ijo-aguda “catholic” eleyiti o ka obinrin si eni ti won seda ni ipele keji.
“Polas Rasul” so bai pe: “Mo fe ki e mope olori gbogbo awon okunrin ni “mesiah” atipe olori obinrin ni okunrin, olori “mesiah” si ni Olohun....dajudaju okunrin ko leto lati bo ori re nitoripe aworan ti Olohun ya ni ti O si gbe titobi fun, a mo obinrin iyi okunrin ni o je nitoripe okunrin ko wa latara obinrin bi kii se pe obinrin lowa latara okunrin, atipe dajudaju won ko seda okunrin nitori obinrin bi kii se pe obinrin ni won s’eda nitori okunrin, nitori eleyi o soranyan fun obinrin lati ni olowo-ori ti yio je ade-ori re nitori awon “malaika”.
Ni paapa awon eko esin mesiah o ti pa ndandan fun obinrin lati maa teriba fun oko re ki o si maa te le ni titele afoju, “Polas” so bai pe: “Mo pe eyin obinrin e maa teriba fun awon oko yin gegebi ti oluwa, dajudaju okunrin ni olori obinrin gege bi “mesiah” ti je olori awon agba-ijo soosi”.
“Bernard Shaw eleko ede oyinbo” so bai pe: “Ni asiko ti obinrin ba ti l’oko gbogbo nkan-ini re ti di ti oko re ni ibamu si ofin awon geesi”
Eleyi je ibamu si bibe-gbere toko-taya ati ailopin re eleyi ti esin ati ofin se ni oranyan, gbogbo bo tile wu ki ikorira de ogongo to larin oko ati iyawo ti awon isoro si nfeju si won ko gbodo ko ara won sile sugbon won ni ona abayo lo sibi ipinya ti ara eleyi ti yio so deto fun okunrin lati yan ololufe lobinrin miran layo, bakanna yio so deto fun obinrin ni tire latiyan ale ati ayanfe.
Bakanna lo se wa nibi isesi ipakoda okan ninu oko abi iyawo, ko leto fun eyi tin be ni aaye lati se igbeyawo leekan si. Ibajade eleyi nipe obinrin je eni yeye, ko si ni ojuse rara ni awujo, eleyi ti opepe losi bi iwa ibaaje si awujo iwo-oorun (geesi) leyi ti omu olopolo awon olaju ninu won mo pepe lo sibi fifun enikookan ninu awon enia awujo yala okunrin ni tabi obinrin ni eto ominira pombele lai si onde kankan nibe ni eyi ti iserisi aburu pada je jade ni awujo wonyii, ti abajade re si isemi ti awon awujo yi nlo ni isin-yi nibi jiju enia le pelu bose fe ati jija okun-ebi, gbogbo eleyi loje iyorisi fun adadaale “soosi” ile-ijosin awon yehudi ati nasara ati irori re ati awon ofin abosi re leyi ti o tako adamo omo-enia todara.

Áwon eto obinrin ninu islam

Leyin iwoye yajo-yajo yi si awon eto obinrin ati awon ipo re ni awujo omo-enia siwaju ihan islam, a wa ni lati woye si ipo re ati awon eto re ti islam se ni oranyan fun. Obinrin ni ninu islam awon eto ajoni ati awon eto adani. Ninu awon eto obinrin ajoni ninu islam:
a). Obinrin da gegebi okunrin nibi ilaborun awon ofin sharia nitoripe o se ni oranyan fun deede ohun ti o se ni oranyan fun okunrin na, nigbati awon monjemu ilabonilorun esin ba ti pele lori leyi ti se (jiju gbogbo-ara le fun Olohun “al’islam”, bibalaga, pipe lakai) nibi irun kiki, yiyo saka, awe gbigba ati sise haji. Sugbon Olohun-oba olofin saa lesa pelu sise apakan awon ofin sharia ni fifuye fun gegebi fifi irun ati awe sile ni asiko nkan-osu re ati ni asiko eje ibimo, ti yio si san awe pada ni asiko imora re, iyen ko je nkankan ju sise akiyesi ipo ara ati emin re ni asiko nkan-osu ati eje-ibimo.
b). Obinrin da gege bi okunrin nibi esan ati ijiya ile-aiye ati orun, Olohun ti ola re ga ju so bai pe:
Itumo: (Enikeni ti o ba se ise rere lokunrin tabi lobinrin ti o si je olugbagbo lododo, Awa yio jeki o lo igbesi aiye ti o dara, bakanna A o san won ni esan won pelu ohun to da ju ti nwon se nise lo.) Surotu an-nahli: 97
d). Obinrin da gege bi okunrin nibi jije enia re, kii se orisun aburu, kii si se ohun ni okunfa jijade Adamo – ki ola Olohun maa ba – ninu alujanna, bakanna ni kii se eya kan ti o kere si okunrin gegebi awon elesin ti o gbawaju ti nso, Olohun ti ola re ga ju nso bai pe:
Itumo: (enyin enia ! E beru Oluwa yin, Eni ti O seda yin lati ara emi kansoso o si se eda aya ré lati ara ré, O si tan opolopo okunrin ati obinrin kalé lati ara awon mejeeji, ki e si beru Olohun, Eni ti e fi nbe ara yin ati okun-ibi, dajudaju Olohun je oluso lori yin) Surotu an-nisaai 1
Olohun se alaye ninu “aaya” wonyi pe ohun seda eya meji ako ati abo lati ara ipile kan soso. Kosi iyato ninu ipile eda, kosi si iyato larin awon mejeeji nibi jije enia, bakanna ni gbogbo won ti ri. Pelu eleyi ni islam fi fagile ohun ti o tan kale ninu awon ofin abosi nipa eto obinrin, leyi ti won nfi lero ‘pe obinrin je eda kan ti o kere si okunrin nipo, leyi ti o wa niise pelu iye nibi imoko fun ninu opolopo awon eto re ti o je ti omo-enia, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Awon obirin omooya awon okunrin ni won je” Abu-daud
e). Obinrin da gege bi okunrin nibi oranyan siso omoluabi re ati didaabo bo aponle re, won si se li leko agbeere (sina) mo ati ifowo abuku omoluabi re ni okunfa idiya jeni, Olohun ti ola re ga so bai pe:
Itumo: (Awon ti won pe (pansaga) mo awon obinrin ti won kii se oni pansaga, lehin ti won ko ri eleri merin mu wa, e na won ni ogorin egba, e ko si gbodo gba eri won lailai, awon eleyi ni poki). Surotu an-nuur 4.
e). Obirin da gege bi okunrin nitoripe o ni eto si ogun-jije bi okunrin ti ni eto si, Olohun ti ola re ga ju nso bai pe:
Itumo: (Awon okunrin ni ipin ninu ohun ti awon obi ati ibatan (won) ba fi sile (ku), obinrin na ni ipin ninu ohun ti awon obi ati ibatan (won) ba fi sile (ku) ninu eyi ti o kere tabi opo re, ipin ti a ti pinnu re ni). Surotu an-nissai 7.
Ayah yii fi ipin obinrin rinle ninu ogun-jije lehin gba tosepe koni ipin kankan nigba aimokan, koda ohun aje mogun loje gegebi won ti jogun awon nkan igbadun, Olohun ti ola re ga ju nso bai pe:
Itumo: (Enyin onigbagbo ododo, ko leto fun yin lati mo gba dukia awon obinrin ni tulasi. Beni e ko gbodo ba won lo pelu ilekoko ki e le gba apakan ohun ti e fun won..). Surotu an-nisaai 19.
“Umar omo khattob” – ki Olohun o yonu si – so bai pe: “Mo fi Olohun bura a kii ka obinrin kun nigba aimokan titi ti Olohun fi so ohun ti o sokale nipa won ti O si pin ohun ti o pin fun won” Sohihu muslim (1108/1479).
f). Obirin da gege bi okunrin nibi pipe eda ati ominira sise boti fe nibi dukia ti o ni ati tita ati rira ati eyi ti o jo iru fe bayi ninu awon sise botiwuni pelu dukia laisi oludanilowoko kan fun u tabi fifi aala si sise botiwu ayafi nibi eyi ti inira ba wa nibe fun u ati eyi ti o ba tako ofin Olohun, Olohun ti ola re ga ju lo nso bai pe:
Itumo: (Enyin ti e gbagbo e maa ná ninu ohun ti o dara ninu eyi ti e se nise). Surotu al’baqorah 267.
Olohun ti ola re ga ju tunso bai pe:
Itumo: (Dajudaju awon ti o ju owo-juse sile fun Olohun ni okunrin ati ni obinrin, ati awon onigbagbo ododo ni okunrin ati obinrin, ati awon ti o tele ti (Olohun) ni okunrin ati obinrin, ati awon olododo ni okunrin ati ni obinrin, ati awon onisuru ni okunrin ati ni obinrin, ati awon ti npaiya Olohun l’okunrin ati l’obinrin, ati awon ti o ntore ni okunrin ati ni obinrin, ati awon ti o ngbawe ni okunrin ati ni obinrin, ati awon t’onso abe won l’okunrin ati l’obinrin, ati awon ti o nranti Olohun ni opolopo (igba) ni okunrin ati ni obinrin, Olohun ti pa lese de won aforijin ati esan ti o tobi). Surotu al- ahzaab 35.
g). Islaam ka aponle obinrin si apere jije omo-enia ti o dara, eni ti o pe ti o je eni-esa, ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe:
Itumo: “Eni ti o pe ju ninu awon onigbagbo ododo ni igbagbo ni eni ti iwa re dara ju lo, awon ti won loore ju ninu yin ni awon ti won dara ju ninu yin si awon obinrin(Iyawo) won” Bukhari logba wa.
h). O se loranyan fun obinrin bi o ti se loranyan fun okunrin wiwa mimo (eko) ati kikoni ni mimo, – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe:
Itumo: “wiwa mimo oranyan loje fun gbogbo musulumi” Sunanu ibn majah.
Ni paapa awon alfa onimimo ti fenuko lori pe gbolohun “musulumi” ni Hadisi yi ko okunrin ati obinrin sinu.
i). Obinrin se deede okunrin nibi rire ati kiko won leko, okookan ninu won lo ni eto si ki won re ni rire ti o dara ki o si dagba ni didagba ti o sunwon. Bakanna ni islam ka rire awon omobinrin ati ninawo lewon lori ninu awon okunfa wiwo “alujanna”. Eleyi je ninu ohun ti awon obinrin fi lekun ju awon okunrin lo. Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Eniti o ba ni omo-obinrin meta ti o si se suru lori won, o fun won ni ounje, o fun won lomi, o si ra aso fun won ninu owo ati ise-owo re, won yio je gaga fun nibi ina ni ojo igbehinde” Al’bukhory.
i). Obinrin da gegebi okunrin nibi oranyan gbigbe ojuse atunse awujo ru nibi pipase daada ati kiko iwa ibaje, Olohun ti ola re ga ju so bai pe:
Itumo: (Onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin apakan won je ore apakeji, won yoo ma pase iwa rere lase (fun enia), won yoo si mo ko iwa buburu (fun enia), won yio si mo gbe irun duro, won yio si mo yo saka, won si tele ti Olohun ati ojise re, awon eleyi ni Olohun yio ke won, dajudaju Olohun ni Alagbara Ologbon) Surotu at-taubah 71
j). Obinrin da gege bi okunrin nibi gbigbani sile (fifunni ni idabo bo) Olohun ti ola re ga ju lo nso bai pe:
Itumo: (Ti kan ninu awon osebo ti o ba wa idabo bo re, ki o dabo bo ti ti yio fi gbo oro Olohun, leyin na ki o si mu de aye ifaiyabale re) surotu at-taubah 6.
– ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Atipe sise adeun awon musulumi fun awon keferi okansoso ni, eni ti o kere ninu won da gegebi eni la won, eni ba wa tu okun adeun musulumi kan ibidandan Olohun ati awon malaika ati awon enia pata yio maa ba, won ko nii gba lowo re ise-oranyan ati asegboore” Sohihu bukhori 1160/3008.
Eleyi ni eto ti o fese rinle fun awon okunrin ati awon obinrin lori isesi kanna, nitori hadisi “umu-ani” omo “abi-tolib” to sope: “Mo lo sodo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – ni odun ti won si makka mo ba ni eni ti nwe ti Fatimoh omo re obinrin ta gaga fun. O so ‘pe: Mo wa salamo si, o (ojise Olohun) wa so ‘pe: ta ni yen? Mo wa sope: Emi Umu-ani omo Abi-tolib ni, o wa sope: Moraba Umu-ani. Nigbati o wa we tan o kirun raka mejo ni eni ti o da aso kan bora, nigba ti o wa kirun tan, mo sope iwo ojise Olohun: Omo iya mi Aliy – ki Olohun yonu si – ngbero lati ba okunrin kan ja ti mo fun ni aabo (Fulanu omo Ubairo), ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – wa so bai pe: Papaa a ti daabo bo eni ti o ba fun ni aabo ire Umu-ani” Umu-ani sope igba na je asiko iyaleta” sohihu bukhari 141/350.
Eleyi ni ipo obinrin ninu islam. Dajudaju Obinrin a ma daabo bo awon musulumi. Lati odo Abu-Huraira, lati odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Dajudaju obiNrin a ma di ijo mu” o tumo si pe: A ma daabo bo (ijo) awon musulumi...sunanu At-tirimisi 141/1579.
Ki aloo mo wipe awon apakan alamori wa leyi ti o je adayanri fun awon okunrin yato si awon obinrin ni eyiti islam ko si fi won se deede arawon nibe, a o menu ba nigbati a ba nsoro nipa awon iruju eleyi ti awon ota esin tan ka nipa obinrin.
Ninu ohun ti o se Pataki ni mimo ipo ati aye ti obinrin wa siwaju ki islam to de ati ipo ti owa leyin gba ti Islam de, ki ipo aponle ti o wa fun obinrin ninu islam le ba a fojuhan yeke-yeke.
A mo awon eto adani ti o wa fun, islam woye si obinrin ni iwoye ti o kari to npepe si nini akolekan nipa re ati fi fun ni awon eto re nibi gbogbo ipele isemi re lati igba bibi re titi di asiku iku re. kii se nibi ipele kan soso nikan, islam se akolekan re nigba ti o je odomobirin, o si se akolekan re nigba ti o di iyawo, o tun se akolekan re nigbati o di iya, o si tun se akolekan re nikehin gegebi obinrin kan ninu akojo awon obinrin musulumo, a o pada rekoja lo sibi awon eto re pelu ni soki nitori pipaya fifa oro gun, eniti o ba fe mo alekun nipa re ko seri lo sibi awon tira agboye esin (fikiu) eleyi ti o se alaye akori yi.
Awon etọ rẹ ninu islam nigbati o je odomobirin:
Etọ nigba isemi: Olohun oba (afomo Re oba ti ola Re ga) se ni oranyan fun awon obi-mejeeji lati ma se amojuto isemi awon omo won, yala won je okunrin tabi obinrin. Osi se pipa won ni esa ti o tobi, olohun ti ola Re ga jo lo nso bai pe:
Itumo: (Atipe ema se ma pa awon omo yin nitori ipaiya osi. Awa ni an se ije imu won ati fun enyin na. Dajudaju pipa won je ese ti o tobi) Suratu al-isrooi 31.
O wa se Nina wo le won lori lokunrin ati lobirin ni eto ti o je oranyan ni eyi ti sise ati diduro fun re je oranyan lori baba lati igba ti won ba ti wa ni olé ninu awon iya won, Olohun ti ola Re ga ju lo nso bai pe:
Itumo: (Ti won ba si ni oyun nigbana ki e maa nawo fun won titi won yio fi bi oyun inu won) suratu at-tolaaq 6.
Eto re nibi mimu-oyan: Papaa Olohun oba (afomo Re oba ti ola Re ga) ti se ni oranyan sise daada si awon omo, okunrin ni tabi obinrin, bakanna lose nini akolekan si won ni oranyan ati dide si amojuto won ati fifun won ni awon ohun ti won nfe nibi pipese isemi ti o dara fun won. Islam si se awon yii ninu ojuse awon omo lori awon obi won, Olohun ti ola Re ga ju lo so bai pe;
Itumo: (Ati ki awon abiyamo ma fun awon omo won lomu mu ni odun meji gbako fun eni ti o ba fe se asepe ti ifun omo lomu mu; ije, imu ati aso ni wiwo won se ni oranyan fun eni ti won bi-mo fun ni ona eto) Suratu al-baqoroh:233.
Eto re nibi titoju ati rire: Olohun oba-asofin ti se ni oranyan lori awon baba nini akolekan rire awon awon omo won okunrin ni won je ni o tabi obinrin ni rire ti ara ati ti lakai ati ti rire si bi ofin Olohun (sharia), - ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe: “O to ni ese fun omo-enia ki o yin awon to n toju nu (lai ko won leko)” Ibn hibban 10 (51/4240).
Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba – tun so bai pe: “Gbogbo yin ni adaranje, gbogbo yin ni won yio si bi lere bi o ti da eran re je, adaranje ni asaju (imamu) je won yio si bi lere bi o ti da eran re je, adaranje ni okunrin je lodo awon araale re won yio bi lere bi o ti da eran re je, adaranje ni obinrin je nile oko re won yio si bi lere bi o ti da eran re je, adaranje ni omo-odo je nibi dukia oga re won yio si bi lere bi o ti da eran re je” sohihu bukhori 1 (304/853).
Bakanna ni o tun leto; sisa awon oruko ti o dara mu fun won. Iya ni eni ti o leto lati setoju awon omo ju baba lo nigbati ifanfa ati ipinya ba sele larin oko ati iyawo. Islam gbe sodo iya lati se itoju re nitori pipe anu ati ike re (iya) lori awon omo opo ju ti baba lo pelu bamu si Hadisi Amru omo shuaibu tolo bayi: dajudaju obinrin kan sope: Iwo ojise Olohun; omo yi inu mi ni o ti jade, omu mi ni o si mu, yara mi ni o si gbe, baba re si ti ko mi sile, o si fe fi agidi jagba lowo mi. Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – wa so bai pe: “Iwo ni o leto si ju nigbati o ko ba ti ni oko miran” Sunanu abi daud (283/2276).
* Etọ re nibi sise ige, aanu ati ike fun: Awon Obinrin je eni ti o ni bukata awon wonyi gegebi bukata won si omi ati ounje nitoripe awon irufe iwa won ni ilapa dada ninu emi won ati ihuwasi won. Islam je esin ike, ige, aanu ati ise-aponle si eniti ona re jin, ki wa pelu eni ti ona re sunmo. Lati odo Abu-huraira – ki Olohun yonu si – o so pe: “Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba - fi enu ko Al-Hasan omo Aliy” lenu larin igba ti Al’aqro' omo Habis” wa ni odo re, “Al’aqro' ba so pe: Omo okunrin mewa ni mo ni, mi o fi enu ko okan lenu ri ninu won!!! Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba - wa wo odo re, leyin na lo wa so ‘pe: “Eni ti ko ba ma se ike enia, won ko ni se ike re” Sohihu al-bukhari 5 (2235/5651).
* Eto re nibi kiko eko: Islam se wiwa mimo ni oranyan fun gbogbo musulumi lokunrin ati lobinrin,ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba - nso bai pe: “Wiwa mimo oranyan loje fun gbogbo musulumi” Sunanu ibn mojah 1/8 (224) sohihu jami’ (3913).
O tun wa se kiko awon obirin gangan leko ninu awon okunfa ilopo ere ati esan, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba - nso bai pe: “Eyikeyi okunrin kan ti erubinrin kan ba mbe lodo re, o wa ko imo ni kiko ti o dara, o tun ko leko ni kiko ti o dara, leyinna o wa bo okun eru lorun re o tun wa fi saya, esan meji ni eru fe enibe yio gba” Sohihu al’bukhari 5/1955 (4795).
* Eto re nibi sise deede: Ofin sharia se deede ati dogba loranyan larin awon omo pelu agboye re ni eyi ti o kari, ko si iyato larin ibagbe pelu ike ati aanu awon obi mejeeji larin awon omo, okunrin ni won tabi obinrin, fun oro Olohun ti ola Re ga ju to so bai pe:     
Itumo: (Dajudaju Olohun npa ase dede sise ati ise rere ati ki a ma fun awon ebi ni eto won, O si nko fun nibi iwa ibaje ati iwa buburu ati rukerudo. O nse ikilo fun yin ki e le ba gba ikilo) Surotu An-nahli 90.
Lati odo “An-nu’mon omo Bashir” – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o nso bai nigbati o wa lori ‘mimbari’ ‘pe: “Baba mi fun mi ni ebun kan, “Amrotu omo Rowahah” wa so pe: mi ko ni yonu si i titi ti oo fi so ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba, o wa lo ba ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba - o wa so fun pe: Mo fun omo mi lati ara “Amrotu omo Rowahah” ni ebun kan, o si pamilase wipe ki un fi o se eleri iwo ojise Olohun lori re. Ojise Olohun wa so wipe: Nje o fun awon omo re yoku ni iru re bi? O so pe: rara. Ojise Olohun wa so pe: E paiya Olohun ki e si ma se deede laarin awon omo yin” O so pe: baba mi ba seri pada o si gba ebu to fun mi pada”.
Awon eni na da, awon ti won n so pe dajudaju islam gbe eto awon obinrin ju sile, nibo ni won ti ri oro yi ?
* Eto re nibi sise esa oko: Islam se aponle irori omobinrin nipa oko nini o si kaa si okan ninu awon mejemu fun iso yigi, o fun ni eto lati sope mo gba tabi mo ko fun eniti oba denuko. Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe: “Won ko ni ma fi abileko loko titi won yio fi gba ase lowo re, won ko si ni ma fi omoge loko titi won yio fi gba iyonda lowo re. Won wa sope: Iwo ojise Olohun bawo ni iyonda re? O wa sope: Ohun ni ki o dake”Sohihu Al-bukhari 5/1974 (4843).
Kosi eto fun baba re tabi alasunmo ti o ni ase lori re lati jenipa lori eni ti ko fe ninu awon oko. Obinrin ti won ba fi loko lai si iyonu re nibe o ni eto lati bere fun titu igbeyawo na ka pelu Hadisi “Khansau omo Jidham Al’ansoriyyah” “O wipe: Baba re fi loko ti o si je adelebo, sugbon ko yonu si, o wa lo ba Annabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – Ojise Olohun si tuu igbeyawo naa”. Sohihu Al-bukhari 6/2547 (6546).
Ni paapa awon itosona Annabi abiyi ti fi rinle nini akolekan pelu awon omo obinrin ati jije-dandan sise aponle won ati sise daada si won ati gbigbo bukata won. Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe: “Eni ti o ba ni omo-binrin meta tabi omoya lobinrin meta, tabi omo-obinrin meji tabi omo’ya lobinrin meji ti o si se amojuto won daada yio wo alujanna” sohihu ibn hibban 2/189 (446).
Islam ka nini akolekan pelu awon omo-obinrin ati sise daada si won si okan ninu awon okunfa wiwo alujanna, ki iye le je ise ni lojukokoro fun awon obi mejeeji pelu won lati le baa ma rankan esan ti nbe lodo Olohun. Lati odo Aisha iya awa mumini – ki Olohun yonu si – o so bai pe: “Obirin alaini kan wa ba mi ti o gbe omo re obinrin meji dani mo wa fun ni eso dabidun meta lati je, o wa fun okookan ninu awon omo re mejeeji ni eso dabidun kookan, o wa fi okan ti o ku senu lati je e, awon omo re obinrin mejeji ba tun bere re eyi to fi senu, o ba tun pin eyi ti o fe je fun awon mejeeji, isesi re yi wa yami lenu, mo wa salaye ohun ti o se yi fun ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – ojise Olohun wa so ‘pe: “Olohun ti so alujanna di oranyan fun pelu re, tabi o ti bo okun ina kuro lorun re” Sohihu muslim 4/2027 (2630).
Gegebi o ti je pe ofin sharia pase deede ati dogba larin awon omo okunrin ni tabi obinrin nibi awon alamori ti a foju ri bakanna ni o pase sise dogba nibi awon alamori nina owo lori won. Ko leto lati gbo fun okunrin ju obinrin lo tabi obinrin ju okunrin lo nibi fifun-ni ni nkan ati awon ebun bakanna ni gbogbo won ti ri, lati odo “An -nu’mon omo Bashir” o so ‘pe: “Baba mi fi apakan dukia re ta mi lore, Iya mi “A’mrotu omo Rowaahah” wa sope: mi ko ni yonu si titi o fi f'ojise Olohun jeri, baba mi ba gbera lo sodo ojise Olohun lati fi jeri ohun ti o fi ta mi lore, Ojise Olohun wa so ‘pe: Nje gbogbo awon omo re ni o se eyi fun ? O so ‘pe: rara. Ojise Olohun wa so pe: “Eberu Olohun o, ki e si ma se deede larin awon omo nyin” o wa seri pada, o si da ore na pada lowo mi” Al-bazar 1893, Al-haythamy 8/156, Al’albany 2994.
Alamori ase sise dogba ati deede ko duro lori awon alamori ti o han nikan, bakanna ni o tun debi awon alamori ti omo-enia ko le ni akaakun re. Islam pase sise dogba larin awon omo nibi fifi enu ko won lenu, “Anas” – ki Olohun yonu si – gba egbawa pe: “Ara kunrin kan joko pelu Annabi – ki ike ati ola Olohun maa ba -, omo okunrin re wa wa sodo re, ogbe osi fi enu ko lenu, o si fi joko sinu yara re, leyin na omo re obinrin wa sodo re, o gbe ohun naa, o si fi joko si egbe re, Annabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – wa so fun pe: o ko se deede larin awon mejeeji”. Otunmo si ko se dede larin omo okunrin ati omo obirin nibi fifi enu ko enu” Al’bazar 1893, Al’haythamiy 8/156, Al’albany 2994.
Ninu ohun ti o da nigba to jepe a si wa ni abala oro-siso nipa akolekan islam pelu awon omo, ki a toka si pelu ohun ti o mo ni soki si akolekan islam pelu awon omo orukan nitori ohun to nbe fun awon omo orukan ninu oripa to lewu lori emi omode ati eleyi ti o jepe o seese ki o mu ko jala nigba ti o ba wa ni awujo ti kii se amojuto awon eto re, ti kii si dide si awon ohun ti o fe ti kii si boju wo ni wiwo aanu ati ike.
Papaa islam ti se akolekan omo orukan okunrin ni tabi obinrin pelu gbogbo akolekan, o wa se ti toju re ati nini akolekan pelu re ni oranyan lori awon alasunmo re, ti ko ba wa ni awon alasunmo o je oranyan lori ijoba esin lati se akolekan, ati lati re.
Adeun iya nla ti wa lati odo Olohun fun eni ti nje ohun-ini omo-orukan ti si nra awon eto re lare, Olohun tola re ga ju so bai pe:
Itumo: (Dajudaju awon eniti o je ohun-ini omo-orukan ni ti abosi, ina ni won je sinu ikun won, won yio si wo ina elejo fofo) Surotu An-nisai 10.
Atipe ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Emi yio ma fi owo-lile mu fun yin eto awon ole meji omo-orukan ati obirin” Al’mustadrok 1/131 (211), Al’albani 1015. Itumo fifi owo-lile mu ni: Ma mo se afati ese si odo eni ti o ba nra awon eto awon mejeeji lare ti o si n sa bosi won ti o si nfi suta kan won.
Bakanna ni ikilo ti wa nipa jijagbe mo o ati nini-lara, Olohun tola Re ga ju lo so bai pe:
Itumo: (Atipe e mase ni omo-orukan lara) SurotuD-duha 9.
Awon ofin Olohun(Shariah) se iseni loju kokoro nipa ije alafeyin ti fun omo-orukan ati sise daada si. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe: “Emi ati olusamojuto omo-orukan bai niwa ninu ogba alujannah, O wa na ika-ilabe ati ika arin soke o wa ya mejeeji” sohihu Al-bukhari 5/2032 (4998).
Bakanna lo rinle sise ni loju oyinyin lori nini aanu ati sise daada si won, Ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Nje o fe ki okan re o fele ki o si ma ri bukata re gbo ? ma sike omo-orukan, ma fowo pa lori, ma fun je ninu onje re, okan re yio fele, o si ma ri bukata re gbo” At-tabarani.
Gege be na ni islam se akolekan awon omo ti won sonu (Lakiitu) okunrin l ni tabi obinrin. Awon won yii ni awon omo kekere ti won ko mo awon obi won. Ninu eto re lori awon musulumi ati orilede islam ni lati ni akolekan pelu re gege bi omo-orukan. Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Nibi gbogbo ohun ti enia ba se fun abemi ni esan wa fun” Albukhari 2/870 (2334).
Pelu awon akolekan yi, a ti fun awujo ni orike meji ti o dara ti yio ma dide si oranyan won, ti won yio si ma semi ni sisemi ti o to larin awon abara (enia).

Awon eto Obinrin ninu islam niti jije iyawo:
Olohun tola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (Atipe ninu awon ami re(Olohun), O da awon aya fun yin ki e le ba ma ri ifayabale lodo won, O si se ife ati ike si aarin yin. Dajudaju awon amin nbe ninu eyi fun awon enia ti o nronu) SurotuR-ruum:21.
Ninu awon amin re ti nda lori titobi re ni siseda fun abara-enia lati ara won awon iyawo ki apakan won le ma fi aiyabale si odo apakji, ki won si le mo ri isinmi fun ara won ati ifarasin fun emi won.
Iyawo ninu islam je opo awujo eleyiti o duro le lori ati opo-ipile eleyi ti ile awon olugbagbo duro le lori. Islam se awon eto kan loranyan fun ati awon ojuse kan. Bakkanaa o tun se awon eto kan ati awon ojuse kan loranyan le lori ni idakeji. Ninu awon eto re ati awon ojuse re:
1). Eto re nibi owo-ori:
Owo ori je oranya ati fifun-ni ti o je dandan, Olohun Oba se loranyan fun obinrin lori okunrin, ko leto fun awon alasunmo re ki won o gba nkankan ninu re lai si iyonu re nibe ati fifowosi re. Bakanna naa ni ko si oyigi ayafi pelu re, eleyi si je itokasi ti ko si iyemeji nibe lori eto obinrin nibi ni-ni dukia. Olohun ti ola Re ga ju lo so bai pe:
Itumo: (E fun awon obinrin ni owo-ori won, sugbon bi won ba fi inu didun yonda nkankan ninu re fun yin funra won, nigbana egba pelu ife) Surotu-nisai: 4.
Eto obinrin eleyi, ko leto fun oko nigba ti o ba ko iyawo re sile ti o si jepe kikole na waye lati odo re (oko) ko gba nkankan ninu owo-ori re eleyi ti o fe le lori, Olohun (ti ola re ga ju) ti salaye aida alamori yi, Olohun ti ola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (Bi eba fe fi iyawo kan paro si aye iyawo kan ti e si ti fun okan ninu won ni opolopo oro, ki e ma se gba nkankan (pada) ninu re. E o ha gba a niti adapa iro ati niti ese ti o han gbangba * Bawo ni e se le gba a pada nigbati o je pe e ti wole to ara yin ti won si ti gba majemu ti o nipon lowo yin.) surotuN-nisai: 20-21.
Olohun ti ola Re ga ju tu nso bai pe:
Itumo: (Enyin onigbagbo ododo, ko to fun yin lati lati gba dukia awon obinrin ni tulasi. Beni e ko gbodo de won mole ki e le gba apakan ohun ti e fun won, ayafi ti won ba se iwa ibaje ti o foju han, e si ma ba won lo pelu daradara. Bi e ba korira ikankan lara won, ti Olohun o si fi opolopo ore sinu re) surotuN-nisai 19.
O mbe ninu aaya alaponle yii ifowosoya fun eto iyawo ti Olohun Oba -ti ola re ga ju se alaye re, lara re: - sise jijogun obinrin pelu ai fe re leewo. Awon larubawa siwaju islam – bi a ti menu ba saaju– nigbati oko ba ku awon alasunmo re yio dide si iyawo re, ti o ba wu apakan won o le fe, ti o ba si wu o le fe fun eni ti o wu, ti o ba si wu o le de mole, ti yio si ko fun lati loko, o wa da gegebi nkan elo ti won ni pelu ogun jije.
Leyinna Olohun tun se alaye jije-eewo ki oko o de iyawo re mole ni ti inira lati le ba fun ile mo, gegebi ki o ma bu tabi ki o ma na tabi ki o ma je dukia re lo naa ti o leto tabi ki o ko fun lati jade tabi ohun ti o ba jo be ninu suta, nitori ki o le sanwo emi fun lati je oko re yonda re.
Papaa sharia se leto fun okunrin lati se iru fe awon won nigba ti iyawo re ba se ise agbere (sina) lati fi gba owo-ori re eyi ti o fi fe leyinna yio jina si pelu kiko sile.
Leyinna Olohun pase oranyan ibalo okunrin pelu iyawo re pelu daada ati pelepele.
2). Eto re nibi dogba ati deede:
Eleyi ni nigbati okunrin bani ju iyawo kan lo, o je oranyan fun ki o mo se dogba larin won nibi jije, mimu, wiwo, ibugbe ati ibusun. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Eni ti o ba ni obiNrin meji, ti o wa fi si odo okan ju ekeji lo, yio wa ni ojo-igbehinde alukiyamo ti egbe re kan yio te” Sohihu ibn hibban 10/7 (4207) & (2077).
3). Eto re si nina owo le lori:
O je oranyan lori oko ki o ma nawo fun iyawo re bi o ti ba asa mu nibi pipese ibugbe ti o boju mu ati pipese awon ohun ti o fe ninu jije ati mimu ati wiwo koda ki obinrin na je oloro. Ojise Olohun - ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “E paiya Olohun lara awon obinrin, dajudaju enyin ti gba won pelu amona Olohun, ti e si se abe won leto pelu gbolohun Olohun, o si ti di dandan fun won ki won o ma se ite yin leto fun enikan ti e korira, ti won ba se be, e na won ni nina ti ko ni ogbe ninu, ije-imu won ti di oranyan fun yin ati wiwo won laso nibamu pelu asa” Sohihu muslim 2/886 (1218).
Ki e si ma fun won ninu ni owo eyi ti won ba ni bukata si nibamu si ikapa ati irorun yin, Olohun ti ola Re ga ju lo so bai pe:
Itumo: (Eniti o ni oro pupo ki o na ninu pupo re, eniti a si di won arisiki re ki ohun naa ninu ohun ti olohun fun u. Olohun ko la bo emi kan lorun koja ohun ti O fun, dajudaju Olohun yio mu irorun wa leyin inira.) SurotuT-tolaaq 7.
Ti oko ti ara de ba ko lati nawo fun iyawo re ti o obinrin na si ni ikapa lati mu ninu owo re lai gba iyonda lowo re, o leto fun lati mu pelu odiwon ti yio gbo bukata re pelu Hadisi “Hindu omo U’tbah to so pe: “Iwo ojise Olohun, dajudaju baba “Sufiyanu” okunrin kan ti o lahun ni kii fun mi ni ohun ti yio to mi ati omo mi ayafi eyi ti mo ba mu ninu owo re., Ojise Olohun wa so pe: mu eyi ti yio to iwo ati omo re ni eyi ti o ba odiwon ti o gbajumo fun bukaata re” sohihu Al-bukhari 6/2052 (5049).
Nigbati oko ba kangara ti ko kapa lati nawo fun iyawo re, tabi o pamo fun iyawo re, titi ara fi ni iru fe iyawo be pelu pipadanu owo nina le lori, ti oko re si ko lati wale, o leto fun u lati bere fun titu igbeyawo won ka ti o ba fe be. Lati odo baba “Sunadi” o so pe: “Mo bi Saheed omo Al-musayyibu” lere nipa okunrin ti ko ri ohun ti yio na fun obinrin re ? O so pe: Won yio so piya larin won. Abu sunadi ni: Mo so pe: se sunna ni? Saheed so pe: bee ni sunna ni” “Shafi'i” so pe: Eleyi ti o jo gbolohun saheed pe sunna ni, ohun ni ki o je sunna lati odo ojise Olohun” sunanu Albaihaqi 7/469 (15485).
4). Eto re nibi ibusun ati biba lo:
O wa ninu awon eto ti o se pataki eleyi ti sharia nfe lowo oko lati maa pe ati lati maa se amojuto re si iyawo re lati so kuro nibi awon ohun ti ko ni atunbotan rere. Obinrin gegebi iyawo loo de oko oni bukata si okan ti yio ni aanu si ti yio si le fun, bakanna ni obukaata si okunrin ti yio ma ba sere, ti yio ma fun ni omi ife mu, ti yio si ma fun ni wara ife. Ni paapa, ofin sharia ti ko wiwokoko mo ijosin tori ki enia le baa pe ojuse yi fun hadisi “Salmon Al-faarisi” – ki Olohun yonu si – nibi to ti wipe: O se abewo Abu Dardaa – ki Olohun yonu si – wo sile, ni iya Dardaa nba soro pelu itiju, (Salman) wa so fun pe ki ni o fe ? Iya darda' da lo n pe: Omo iya re ko ni bukata kankan si igbesi-aye ju pe ki o kirun loru, ki o si gbawe losan lo !! Ni Abu-Dardaa ba wole de, o si ki kaabo, won si gbe ounje fun, Salmon ba so fun pe: jeun. O so: Mo gbaawe. Salman wa sofun wipe: Mo fi Olohun bura o gbo do ja awe, lo ba jeun pelu re, leyin na o sun sodo re, nigbati o di ni oru, Abu-dardaa fe gberun duro, ni Salmon ba ko fun, lo wa so fun pe: Dajudaju eto nbe fun ara re lori re, eto si nbe fun Olohun re lori re, ara-ile re na si ni eto lori re, moo gbaawe ki o si mo je osan, mo kirun ki o si tun ma sunmo eleto re, mo fun gbogbo eleto leto re. Nigbati ile ku dede ko mo o wa so fun pe o le dide ni isin ti o ba wu o, awon mejeeji wa dide saluwala won si gberun duro leyin na won gba mosalasi lo (lati lo kirun). Leyinna Abu Darda' lo ba Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – lati salaye ohun to sele fun. Annabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – ba so fun pe: Odo oro ni Salmon so” Sohihu Albukhari 2/694 (1867).
Ibn-Hasm so pe: won se loranyan lori okunrin pe ki o sunmo obirin re ti i se iyawo re, o kere ni eekan ni gbogbo igba ti o ba ti se imora ti o ba nikapa be, ti ko ba wa se be o ti di elese si Olohun ti ole Re ga ju... eri eleyi ni oro Olohun to so pe:
Itumo: (Nigbati won ba mo ra e mo ba won lo ni aye ti Olohun pa lase fun yin) surotul’ Baqoroh: 222.
Ninu eto re lori oko re ni pe ti o ba fi sile lo irin-ajo, ko gbodo lo koja osu-mefa, sugbon ti o ba si se suru lori eyi ti o ba lekun, ti o gbe eto re ju sile ko si aburu be, sugbon ti eleyi ko ba rorun fun, oranyan ni lori oko lati seri pada sile ti o ba nbere fun pipada re ko si gbodo fi lora ayafi pelu awijare ti o lagbara., fun ohun ti Umoru omo Khatob – ki Olohun yonu si - arole keji fun ojise Olohun se nigbati o gbo ti obirin kan nso pe: Opolopo oru ni o ti fowo ra ibusun ni ohun nikan. Ti ko si ri aayo re nibe ti yio ba sere. mi fi Olohun bura pe ti kii ba se ti Olohun ti mo n paya re elomiran o ba ti g’ori ibusun oko re lati gbo jigijigi.
Nigbati ile mo Umar ranse si, osi so fun pe: iwo lo so bai-bai ? O dahun pe: be e ni. Umar bi le re pe ki lo fa? O so pe: Iwo lo ran oko mi jade pelu iko omo-ogun, Umar wa bi Hafsah lere pe: Igba wo ni obinrin le se suru di lai ri oko re ? Hafsah sope: Osu mefa ni. Pelu ise leyi ni Umar fi mo n da awon omo-ogun re pada leyin osu mefa” AbduR-rozaq 7/152 (12594).
Ninu awon eto re bakanna naa ni siso awon asiri re ati imo moo se afihan awon alebu re si enikankan ati imo da osoo bo ohun ti o ba ri tabi ti o ba gbo lodo re ati sise afipamo ohun ti o ba n se laarin won ninu awon ajosepo ti won da ni, ko gbodo je eni ti yio mo so awon nkan wonyi ni awon aye ijoko pelu awon ore, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa - ba so bai pe: “Dajudaju eni ti aaye re buru ju lodo Olohun ni ojo igbehinde ni okunrin kan ti o dawa pelu obinrin ti ohun na si dawa pelu re, leyin na okan ninu won wa lo n fon asiri ikeji kiri” Sohihu Muslim 2/1060 (1437).
5). Eto re nibi ibalo to dara ati ibase ti o rewa:
Ninu eto re ni imo o baa se ni bi baa se ti o rewa ati sise aponle re koda ki o korira nkankan lara re, fun oro olohun ti ola Re ga ju ti o so bai pe:
Itumo: (Ki e si ma ba won lo pelu daradara. Bi e ba korira won, osee se ki ekorira nkankan ki Olohun si fi opolopo rere sinu re) Surotu An-nisai 19.
Nigba ikorira re kogbodo yepere re, ko da o pon dandan fun lati ma ba soro pelu ike, aanu ati sise pelepele pelu re tabi ki o ko sile pelupelu daadaa, Olohun ti ola Re ga ju nso bai pe:
Itumo: (Ikosile eemeji ni, e mu won dani pelu daada tabi ki e fi won sile pelu daada) Surotu Al-baqaroh: 229.
Ati nititori pe pipe obinrin ni bi gbogbo nkan je oun ti ko le sele ni ojise Olohun - ki ike ati ola Olohun maa ba – fi so bai pe: E ma se daada si awon obinrin, dajudaju won seda obinrin lati ara egungun efonha, atipe eyiti o te kokoro ni ara efonha ni oke re, ti o ba gbiyanju lati na gbooro o ma kan, ti o ba si fi sile ko niye ko nigbo ni tite kokoro, e ma se daada si awon obirin” Sohihu Al-bukhari 3/1212 (3153).
Atipe nititori awon ase to to wa nibi isemi loko-laya ni won fi pa oko lase pelu sise suru ati fifi ara da ohun ti o ba n waye lati odo iyawo re ninu ohun ti o korira re lati le so isemi loko-laya, ki osi mo ranti awon daada re nigbati o ba nranti awon aburu re, ojise Olohun - ki ike ati ola Olohun maa ba - so bai pe: “Onigbagbo lokunrin kan ko gbodo ma korira onigbagbo lobirin, ti o ba korira iwa kan lara re, yio yonu si omiran lara re” Sohihu Muslim 2/1091 (1469).
Bakanna o je dandan imo lo pelu re pelu aanu, fifi ife han si ati sise pelepele, - ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba - so bai pe: “Eni ti eemoni re pe ju ninu awon onigbagbo ododo ni eni ti o dara ju ni iwa, atipe awon eni esa inu yin ni awon ti won dara si awon obinrin won” Sohihu Ibn hibban 9/483 (4176)...
Bakanna ni imo ba sere, imo ba se awewa, mimo ba sawada ati mima pa lerin je lara awon eto re, lati odo Aisha – ki Olohun yonu si – dajudaju o so bai pe: “Annabi - ki ike ati ola Olohun maa ba – bami sare idije mo si la, a wa lo igba die ti mo ti sanra, o tun bami sare idije o si la mi, Annabi - ki ike ati ola Olohun maa ba – wa so pe: Eleyi se deede alakokoko” Sohihu ibn hibban 10/545 (4691) sohihu Alirwai (1502) As-sohiha (131).
Papaa islam ka eleyi si ninu eto, - ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe: “Gbogbo ohun ti o ba ti yato si iranti Olohun je nkan ti ko lasu n si, nkan ere ayafi idije merin kan: Idije omo-enia pelu ofa tita, ati kiko esin re leko, ati si sere pelu obinrin re, ati kiko liluwe” Sunanu An-nisai ati Tobarooni.
Bakanna siso dukia re ti o dani. Oko re ko gbodo se nkankan pelu re ayafi pelu iyonda re. ko leto fun ki o mu nkankan ninu re lai si iyonu re ati mimosi re nbe, Olohun ti ola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (E ko gbodo maa je dukia arayin larin ara yin ni ti ibaje) Surotu Albaqaroh:188.
Ninu awon eto re ni mimo ba se ijiroro nipa awon alamori ti o nii se pelu awon eto ile ati awon omo, ati ohun ti o nbe larin awon mejeeji ni awon alamori ajose po. Ko si ogbon ninu ki okunrin maa da irori re lo lai woye si irori iyawo re lokurugba ti o ba ti je ohun ti o to, Olohun ti ola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (Atipe alamori won pelu igbamoran (shuuro) ni arin ara won) Surotu As-suuro 38.
Sise iranlowo fun nibi awon ise ile ati jiji naa si igberaga, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – je eni ti o mo n ran aso re, o si mo nso bata re, o si ma nran awon ara le re lowo nibi apakan awon eto ile. Won bi Aisha leere ‘pe: “Ki ni Annabi– ki ike ati ola Olohun maa ba- mo nse ninu ile? O sope: O mo nba awon araale re sise, ti asiko irun ba si ti to yio bo sita lo kirun.” Sohihu Al-bukhari 1/239 (644).
Imo ji naa si titojubo awon adinku re ni gbogbo-gba, ati mimo to pinpin awon asise re, Ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Nigbati enikookan yin ba de lati irin-ajo olojo pipe, ko gbodo fi oru kanlekun iyawo re.” Sohihu Al-bukhari 5/2008 (4946).
Itumo eleyi ni dide loru lati irinajo ti eni keni ko mo, ti iyawo re na kosi mo, nitoripe o le ri iyawo re lori isesi ti ko ni te lorun ti o le je okunfa ikorira iyawo re.
Otuwa ninu eto obinrin lori ok re imo jina si fifi suta kan pelu awon oro ti yio ko edun okan ba ti yio si mo se alekun ibanuje re, fun oro ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – ti o so fun eni ti o bere lowo re pe: “Ire ojise Olohun ki ni eto iyawo okookan wa lori wa ? Ojise Olohun si da lo n pe: “Ki o mo fun ni ounje ti iwo na ba ti n jeun, ki o mo fun laso wo ti iwo na ba ti n wo so, o ko gbodo na loju, o ko gbodo soro ti kodara si, o ko gbodo deye si ayafi ninu ile.”Sunanu Abi daud 2/244 (2142).
O ni eto lati bere fun kiko oko re sile nigbati ko ba ni fe si mo ti si n korira re, pelu mojemu pe ki o da ohun ti o fun pada ninu owo-ori, ayafi ti oko re ba yonda re fun. Lati odo Ibnu-Abbas: “Jemilah omo Saluul wa sodo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – o si so pe: Mo fi olohun bura mi ko fi enu-egan kan Thabit nipa esin ati iwa re! Sugbon mo korira iwa-keferi leyin gbigba islam mi, nko le mu ikorira re mora mo. Anabi - ki ike ati ola Olohun maa ba- wa so fun pe: “Se o le da ogba-oko re pada fun ?” O ni bee ni. Ojise Olohun - ki ike ati ola Olohun maa ba - wa paa lase fun pe ki o gba ogba-oko re lowo re lai gba alekun.” Sohihu Albukhori.
Bakanna ni o je dandan mimo daabo-bo nibi awon ohun ti o le se okunfa iyepere aponle re ati ohun ti o le ko idoti ba omoluabi re,ojise Olohun - ki ike ati ola Olohun maa ba - so bai pe:”Awon meta ti won ko ni wo alujanna; oluseya-se baba, eni to je okunfa ibaje obinrin, ati obinrin ti nse bi okunrin” Almustadrok 1/144 (244).
Mimo jowu lori re ati mimu jina si awon aaye-aburu, ko si gbodo mu lo si awon aaye awewa, aaye-ibaje, aaye ti kosi itiju nibe ati aaye isekuse, ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba - so bai pe: “Dajudaju Olohun a mo jowu, onigbagbo ododo na si mo n jowu, sugbon owujije ti Olohun ni ki onigbagbo ododo o se nkan ti Olohun ba se ni eewo.” Sohihu Muslim 4/2114 (2761). A mo owu-jije yi gbodo wa ni tun won si pelu ofin Olohun.

Eto re ninu islam ni to ba di Iya
Islam pa se sise daada si awon obi mejeeji pelu opolopo awon aaya ninu Al-qur’an, o si so eto won mo eto re lati se alaye titobi eto awon mejeeji, olohun ti ola Re ga ju lo so bai pe:
Itumo: (Atipe Oluwa re pa lase pe: E ko gbodo sin kinikan ayafi ohun nikan ati ki e si mo se rere si awon obi mejeeji. Bi okan ninu won ba dagba si o lowo abi awon mejeeji, o ko gbodo se si o won bee si ni o ko gbodo jagbe mo won, sugbon ki o ma ba won soro alaponle. Ati ki o re ara re nile fun won niti aanu ki o mo so pe: Oluwa ba mi ke awon mejeeji gegebi won ti ke mi ni kekere.) Suroyu Al-isra' 23-24.
- Islam se adayanri sise rere si iya ati sise daada si ati mimo mo yapa ase re ni ninu awon okunfa wiwo alujannah. Arakunrin kan ti oruko re n je “Jahamoh” wa ba Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba -, o wa so pe: “Ire ojise Olohun mo wa fun itosona re lori lilo oju ogun. Ojise Olohun ki ike ati ola Olohun maa ba – wa so fun pe: Nje o ni iya? O dahun pe bee ni, ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba – wa so pe: lo mo se daada si iya re, dajudaju alujanna nbe ni gigise re mejeeji.” Almustadrok 4/167 (7248).
Atipe ni opolopo igba obinrin je eda kan ti o le, ni eyi ti o mo n je okunfa rira opolopo awon eto re lare lo fa ti islam fi gbola fun lori okunrin ni sise daada si ati I mo lopo pelu re pelu iwa to dara lati le so awon eto ni bi ifowo de ngbere mu. Abi-Hurayrah” – ki Olohun yonu si – so pe: “okunrin kan wa si odo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – o wa so pe: ire ojise Olohun taa ni o leto ju ninu awon enia ki n moo se daada si ju lo ? Anabi da lo n wipe: Iya re. O tun bere: leyina taa tun ni? Anabi so pe: Iya re. O tun so pe: leyina taa tun ni? Anabi so pe: Iya re. O tun so pe: leyina taa tun ni? Anabi so pe: Baba re.” Sohihu al-bukhari 5/2227 (5626).
Itunmo hadisi yi gegebi won ti salaye re ni pe ki o ma be fun iya ipele meta ohun ti o mbe fun baba ninu sise rere si won nitori inira oyun nini, bibi ati fifun loyan, awon alamori meteeta yi da wa fun iya leyinna ni baba yio wa ba kegbe nibi tito.
Iya lo loyun re sikun ti o si nsemi ninu onje ti oun je ati ninu alafia re fun osu mesan leyi ti opo ju – leyinna ni fifun lomu fun odun meji fun eni ti o ba fe lati pe asiko ifomo-lomu gegebi Olohun wa se toka si ninu oro re pe:
Itumo: (Atipe awa so asotele fun enia nipa obi re, iya re gbe sinu pelu ai lera lori ai lera ati ti toju re fun odunmeji, dupe fun mi ati fun awon obi re, Odo mi ni iseri pada si) Surotu Luqumon:14.
- Islam se e leewo mimo se iya ati mimo ta ko ase re ati imo mo pe awon iwo re, ojise Olohun- ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: Dajudaju Olohun ti ola Re ga ju se ni eewo fun yin; mi mo se awon iya yin, ati imo ko yiyo oranyan saka, ati mimo bere ohun ti ko to si nii, ati mimo sin omo-obinrin laaye, O si ko fun yin oro woni-wonpe, ati bi bere ibere ti ko si anfani nibe, ati mimo ra dukia lare.” Sohihu albukhori 5/2229 (5630).
- Mimo te le ati pipe ase re ati aigbodo mo o se e nigbati ko ba ti pase ai da, ti o ba pa se ai da kosi titele fun nigba naa, nitoripe iyonu Olohun siwaju iyonu re, ti tele ti Olohun siwaju ti tele ti re, eleyi ko tunmo si pe ki o wa mo hu iwa-bu si, yio mo se pelepele yio si mo fi ife han si, yio si mo salaye fun pelu irele ati pelepele, gegebi Olohun wa (Oba to gbongbon ti ola Re ga ju) se nsalaye pelu oro re pe:
Itumo: (Bi won ba ngba o ni iyanju pe ki o wa orogun pelu Mi eyi ti ire ko ni imo kan nipa re, mo se tele ti awon mejeeji, ki o si mo ba won lo ni aiye pelu daradara, ki o si tele ona eni ti o seri si odo Mi, lehinna na odo Mi ni ipadasi yin, nigbana Emi yio fun yin niro ohun ti e se nise) Surotu Luqumon 15.
- Atipe ki Olohun wa (Oba to gbongbon ti ola Re ga ju) le salaye titobi iwo obi mejeeji O fi iyonu re sibi iyonu awon mejeeji, ati ibinu re sibi ibinu awon mejeeji, iye nipe ki awon omo le mo se oju-kokoro pi pese isemi ti o dara ti ko ni waala ninu fun won. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba – nso ninu oro re bai pe: “Iyonu Olohun nibi iyonu obi lowa, ibinu Olohun nibi ibinu obi lowa.” Sohihu Ibn hibban 2/172 (429).
Iyonu won ati sise daada si won je okunfa wiwo alujanna, mimu-inu bi won ati sise won je okunfa wiwo ina gegebi ojise Olohun ti salaye re, lati odo Anas – ki Olohun yonu si – o so pe: “Won bi Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – lere nipa awon ese nla, o si so pe: Mimu orogun po mo Olohun, ati sise obi mejeeji, ati gbigba emi enia, ati jijeri eke.” Sohihu muslim.
Abd Allah omo Amr so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Iyonu Oluwa nibi iyonu obi lowa, ibinu Oluwa nibi ibinu obi lowa.” Al-bukhari.
Abi Dardaai, dajudaju so pe: “Mo gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Obi ni eyi ti o loore ju ninu ilekun alujanna, ki o ya mo mojuto awon obi re tabi ki o fi le.” At-tirimisi ati Ibn majah.
- Islam ti sise daada si iya ati baba siwaju awon ijosin asegboore gegebi irun kiki ati ohun ti o yato si, lati odo Abu hurairah – ki olohun yonu si – lati odo Annabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Eni kankan ko soro lori ite ju awon meta lo; Isa omo Mariyama – ki ola Olohun maa ba –, arakunrin kan wa ti won npe ni “Juroiju” o je eni ti mo n se ijosin, o wa mo aaye kan ti o n duro si, ni iya re ba wa ba nigbati o kirun lowo, o wa so pe: Juroiju o ! Juroiju wa so pe: Iwo Olohun mi, iya mi n pe mi mo si n kirun lowo, lo ba gbaju mo irun ti n ki, ni iya re ba pada, nigbati o di ojo-keji iya re tun wa lasiko ti o n kirun lowo, osi tun pe wipe; Iwo juroiju ! o tun so pe: Iwo Olohun mi, iya mi n pe mi mo si nkirun lowo, lo ba gbaju mo irun ti n ki, o tun wa ba ni ojo-keta lasiko ti o n kirun lowo, osi tun pe wipe; Iwo juroiju ! o tun so pe: Iwo Olohun mi, iya mi npe mi mo si n kirun lowo, lo ba gbaju mo irun ti nki. Iya re wa so pe: iwo Olohun mi mo je ki o kuro laiye yi ti yio fi siju wo awon obinrin oni pansaga (sina). Awon omo Isireli wa so nipa Juraiju ati ijosin re, ara binrin kan ti won mo fi juwe ewa ba sope: ti eba fe ki nfi fitina re ma fitina re, lo ba lo si odo re, sugbon ko sijuwo omobirin na rara, ni arabinrin yii ba lo ba okunrin adaranje kan ti o ma n koja legbe aiye ijosin juroiju, o si fi ara re sile fun titi o fi ba ni ajosepo ti o fi loyun, nigbati o bi omo inu re, o so pe juraiju lo ni, won si lo ba ni aaye re won gbe jade won si ba aaye ijosin re je, won si bere si ni na, o wa so pe kini n to mu yin ? won so pe: O ba omobirin alagbere yi se sina o si bimo fun o, o wa so pe: Omo na da? Won si gbewa fun, o wa so pe: E fi mi sile na ki nkirun fun Olohun, o wa kirun nigbati o kirun tan o lo si odo omo naa o si fi owo ba nikun, o wa so pe: Iwo omo yi taa ni baba re ? o si so pe: Lagbaja adaranje ni, won wa koju si Juraiju won bere si ni di mo won si fowo pa lara, won so pe: Ao ba o ko aaye ijosin re pada pelu goolu, o so pe: Rara, e da pada pelu iyepe bi o se wa tele, won si se be....” Sohihu al-bukhari 3/1268 (3253).
Koda Islam gbola fun sise daada si won lori jijagun si oju-ona olohun ti kii ba tii se ogun oranyan ojulowo. Lati odo Abd Allahi omo Amr omo Al’aas – ki olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: “Okunrin kan wa si odo Anabi-Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – o si so pe: ma se ibura fun o lori sise ijira ati jijagun si ojuona olohun, mo nfe esan lodo olohun ti ola Re ga ju. Anabi wa so pe: “Nje o ni eni ti nbe laye ninu awon obi re mejeeji bi ? o ni bee ni awon mejeeji wa, o tun so fun pe: “o si nfe esan lodo Olohun ti ola re ga ju ? o ni bee ni. O wa so fun pe: “Pada lo si odo awon obi re mejeeji ki o si mo lo ba won mejeeji gbe pelu daada.” Sohihu muslim 4/1975 (2549).
- Atipe Islam wa lati se koriya fun awon ajosepo ati lati fun okun-asopo larin omo-enia lagbara ko wa lati ja, o se sise daada si awon obi mejeeji ni oranyan ninu owo nina ati fi fun ni nkan ati oro to dara ati ibagbe to rewa koda ko je pe awon mejeeji yapa si nibi esin. Lati odo “Asma'” – ki Olohun yonu si – o so pe:
 “Iya mi wa bami o si je olumorogun mo Olohun, mo wa bere lowo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – wipe: Iya mi wa bami ni eni ti nrankan pe ki nda okun ibi ohun po, se ki n da okun ibi iya mi po ?Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba wa so fun pe: Bee ni da okun-ibi iya re po.” Sohihu albukhori 2/924 (2477).
- Atipe lati le se musulumi loju kokoro ise daada pelu awon obi mejeeji ni ojise Olohun ki ike ati ola Olohun maa ba fi n se alaye pe dajudaju sise rere ati daada si awon mejeeji je okunfa ti Olohun fi mo gba adua. Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe:zrp==“Awon okunrin meta kan ninu awon ti won siwaju yin se rin ajo titi won fi wole sun ni abe iho, ni okuta kan lati ori apata ba sin won mo inu iho na, won wa so pe nkankan ko le layin ni abe apata yii ayafi ki e be Olohun pelu ise daada yin, okan ninu won wa so pe: Olohun oba mi; mo ni obi meji ti won ti dagba ti won si ti darugbo, mi kii da enikankan lohun siwaju won titi won yio fi mu wara won ni ale, mo wa ko iroju ni ojo kan mi o tete lo si odo won titi awon mejeeji fi sun, mo pese wara ti won yio mu ni ale mo wa ba awon mejeeji ti won ti sun, mo si korira ki ntaari elomiran siwaju won ki won to mu tiwon, mo wa duro ti igba wara si mbe lowo mi mejeeji ni eni ti n reti pe ki won dide loju orun, sugbon won ko ji ti ti ile fi mo, mo si gbe wara naa fun won, olohun-oba kani mo se eley nitori ki nle ri oju rere re lawa ninu ogbun ti a kosi yi. Ogbun naa si la die ni eyi ti ko le gbawon lati jade. Annabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – so pe: ikeji na tun so pe: Mo ni omo-egbon lobinrin kan ti o si je eni ti mo feran ju ninu awon enia, mo si fe lati ba ni ajosepo ti o si ko fun mi, ise wa mu ni odun-kan ninu awon odun; o wa wa si odo mi, mo si fun ni ogorun ati ogun “Dinari” pelu mojemu pe emi ati oun nikan o da wa ni koko, o si se be titi timo fi nikapa lori re, o si so fun mi pe oun ko nigba fun mi ki n ba ohun ni ajosepo ayafi pelu eto, ara wa nimi lati sunmo o, mo si kuro lodo re ti o si je pe ohun ni eni ti mo nife si ju ninu awon enia, mo si fi goolu ti mo fun sile fun, iwo Olohun ti o ba je pe mo se eleyi nitori ki nle ri oju re Re wa lawa ninu ogbun ti a kosi yi, apata tun si ni iwoo ba ti ko le gba won lati jade. Annabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – so pe: iketa na tun so pe: Iwo Olohun-oba mo gba awon osise kan si ise ti mo si fun won ni owo-ise won ayafi okunrin kan ti o fi tie sile ti o si lo, ti eto re si so eso topo titi ti opolopo dukia fi jade lati ara re, o wa pada wa bami leyin igba die, o wa so pe iwo erusin Olohun ba mi mu owo-ise mi, mo si so fun pe: gbogbo ohun ti o nwo yi lati ara owo-ise re ni, ninu rakunmi, malu, agutan ati eru, o ni iwo erusin-olohun ma mu mi sere, mo ni n mu o sere, o si ko gbogbo re lo ti ko fi nkankan sile fun mi, iwo Olohun ti o ba je pe mo se eleyi nitori ki nle ri oju’re Re wa lawa ninu ogbun ti a kosi yi, apata si si tan won si jade.” Sohihu al-bukhari 2/793 (2152).
- Islam se sise rere ati daada si won ninu awon okunfa ipa ese re. Lati odo Abd Allahi omo Umar - ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: “Okunrin kan wa ba ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – o so pe: Iwo ojise Olohun; emi ti se ese ti o tobi kan, nje tituba nbe fun mi bi? Ojise Olohun ki ike ati ola maa ba – wa so fun pe: Nje o ni obi mejeeji ? O ni rara. O ni nje o ni aburo-iya lobinrin ? O ni bee ni. Ojese ni lo mo se daada si.” Sohihu Ibn hibban 2/177 (435). toripe aburo-iya lobinrin ninu islam wa nipo iya, fun oro oun se Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – ti o so pe:”Aburo-iya lobirin da gegebi iya.” Sohihu Al-bukhari 2/960 (2552).
Islam se eto won ni eyi ti yio mo te siwaju koda leyin ti won ba ku tan, lati odo Abi-Hurairah; dajudaju ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Nigbati omo-enia ba ti ku, ise sise yio tan fun ayafi ninu awon nkan meta; ayafi ninu sara ti nsan, tabi imo ti awon enia nse anfani pelu re, tabi omore ti o fi sile ti nse adua fun.” Sohihu Muslim.

Awon eto re ninu islam gegebi obinrin ni awujo awon obinrin
Islam se loranyan fun gbogbo awon musulumi lati mo u wa rere ati daada si, fun oro Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba – ti o so bai pe: “Dajudaju onigbagbo ododo si onigbagbo ododo da gegebi ile, ti apa kan so po mo apa kan. O wa di awon omo-nika re po.” Sohihu Albukhori 1/182 (467).
Ti o ba je aburo-baba lobinrin tabi aburo-iya lobinrin tabi alasunmo lobinrin, nigbanaa yio je kan ninu awon molebi ti Olohun pa se asopo won, ti O si se adeun ijiya fun eni ti o ba ja ni ijiya ti o lekoko, Olohun ti ola Re ga ju lo so bai pe:
Itumo: (Nje e nlero pe ti e ba di alase pe eyin o mo se ibaje lori ile, e o si tun ja okun ebi yin ?) Surotu Muhammad 22.
Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun maa ba tun nso bai pe: “Ko ni wo alujanna; eni ti nja okun-ibi.” Sohihu Muslim 4/1981 (2556).
Bakanna ojise Olohun tun ka sise daada si molebi si okan ninu ohun won yio san musulumi lesan le lori ni ipana-meji. Ojise Olohun-ki ike ati ola Olohun maa ba so bai pe: “Sara sise fun alaini sara kan soso ni, a mo sara sise fun alasunmo sara meji ni, sise sara ati sisa sopo molebi.” Sohihu Ibn khuzaymo 3/278 (2067).
Ti o ba je pe o je kan ninu awon alamuleti eto meji lo wa fun; eto islam ati eto imuleti, Olohun ti ola Re ga ju nso bai pe:
Itumo: (E mo sin Olohun, ki e si mo da n kankan po mo ni orogun, ki e si mo se rere si awon obi yin mejeeji ati awon ibatan ti o sunmo yin ati awon omo-orukan ati awon alaini ati awon aladugbo ti o sunmo yin ati awon aladugbo ti o jina) Surotu An-nisai 36.
O tun se oranyan fun awon aladugbo re ki won o mo se daada si, ki won si mo ran lowo lori latigbo awon bukata re, ki won si mo kun lowo nibi awon ohun to ni bukata si. Ojise olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – so bai pe: “Jibirilu koye-kogbo ni eni ti o n so asotele nibi sise daada si aladugbo mo mi leti, titi mo fi nlero wipe yio wa ninu awon ti yio jogun re.” Sohihu Al-bukhari 5/2239 (5668).
Be ni o tun soranyan fun won ki won ó gbe suta jina si, ki won o si momo soro abuku si, ati ibagbe buruku si. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba – nso bai pe: “Mo fi olohun bura ko ni igbagbo, Mo fi olohun bura ko ni igbagbo, Mo fi olohun bura ko ni igbagbo” Won so pe: Taa ni iwo ojise Olohun ? O ni: Eni ti aladugbo re ko ni ifayabale lati ara aburu re.” Sohihu Al-bukhari 5/2240 (5670).
Won yio mo o so awon iwo re gege bi obinrin, se riranlowo ati gbigbo bukata re ninu ohun ti musulumi yio mo dije le lori. Islam ka sisare si awon obinrin ti won ni awon bukata si okan ninu awon ise ti o ni esan gaju lo. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba nso bai pe: “Eni ti n sare si gbigbo bukata awon opo ati awon alaini o da gegebi olujagun si oju-ona Olohun tabi gegebi eni ti nfi oru kirun ti nfi osan gbaawe.” Sohihu Albukhori 5/2047 (5038).
Awon “Saabe” ki Olohun yonu si won- won je eniti mo n wadi nipa awon aladugbo won papaa-julo awon alaini ninu won ati awon obinrin.Toliha” ki Olohun yonu si – ti gba egbawa pe: “Umoru – ki Olohun yonu si jade ni ale ojo kan lasiko ti oje olori fun awon mumini, mo wa te le leyin, o wa wole sinu awon ile kan leyin na o tun wo ile kan miran, nigbati o wa di ni owuro mo rekoja leba ile na mo si wole, ni mo ba ri iya arugbo afoju kan ti ko le dide, mo wa so fun pe: ki ni ti okunrin ti o wa bi lale ana? O si so pe: o je eni ti n mo se amojuto mi lati igba bai bai, o ma ngbo bukata mi o si ma nbami tun ile se o si ma nba mi da idoti nu. “Toliha” wa so pe: Nje awon ohun ti won nri bi asise Umoru gan ko ye ki won o mo tele nibe ?.” Abu nuhaim.
Eleyi die ninu awon ilana nipa iwo ati awon ojuse, eleyi ti o kojo si abe re awon iwo ati awon ojuse miran ti a ko le menu ba niti pipaya ki oro o mo gun. Pelu eleyi oti fojuhan gbangba fun oluka alaponle yii apakan aworan ti o tan imole nipa aponle islam fun obinrin, eleyi ti ko si saaju ki Islam to o de ati leyin dide re, ti won ko si lee ri irufe awon aponle naa ayafi ni abe bogi Islam ati lilo awon idajo re.


Awon alamori iruju ti won so nipa obinrin ninu islam:

Ninu oun to dara larin isoro nipa eto ati iwo obinrin oun ni si soro nipa awon iruju eyiti awon ota esin Islam fonka lati le mo fi enu egan kan esin Olohun nipa eto obinrin ati iwo re ninu Islam eleyi ti ko si irufe re lati gba ti Islam ti de abi saaju ko to de.
Dajudaju awon iruju eleyi ti won n tokasi nipa obinrin ati awon eto re ninu islam pelu igbedide akojo awon enia lati mo iwoyesi won, bakanna pelu tita-koko sise akojo ijiroro awon oniwadi ijinle o ni awon erogba to paamo eyi to sepe oju fi fun obinrin ni ominira lo gegebi bi won se so lo. Ki lo de ti won mo soro nipa eto awon omode ati eto awon akanda enia ati eto awon olu feyinti lenu ise ati eto awon ole awon eniti won nfi suta kan won lori esin won ati lori isemi won ti awon ota si nje gaba lori ilu won, ti won si n le won jade kuro ni gbogbo aaye. Kilode ti won mo ko akojo lori awon isesi wonyi ayafi lori eto obinrin, botileje pe won mo se waala lori eleyi ayafi nitori awon idikan to pamo.
Ninu idi won yii ni:
* Siseri laika awujo lapaapo kuro nibi ohun ti won pese sile fun ra won si bi awon alamori kan ti won ya aworan won gegebi alamori to se koko tosi se pataki sugbon lairi bee, nititori awon anfani to wa nbe fun awon enia wonyi.
Awa gegebi musulumi ni adiokan asi tun ni amodaju pe awon alamori wonyi ko leto si an pariwo le lori nitoripe ofin esin wa t se alaye won. Awon enia won yii nfi ara won han si aye gegebi olododo oluja fun eto awon obinrin lati le so di okan lara won, leyin na yio wa da gegebi nkan fi sere ti awon iko meji fi nsere ti won yio ma yi kiri bi won ti fe, won yio wa so di ounje fun awon ti won fe lati dede re.
* Won nfe lati fon ibaje ka ati iyepere si awon awujo nigbati o je pe awujo ti iyepere ati ibaje ba ti tan ka si yio rorun fun ota lati je gaba le lori ati lati mo lo oro ati oore ilu bayi fun anfaani awon ota ti won ndede re ati fun awon ti won nrankan si, toripe agbara ilu wonyi ti di oun lo si ibi nkan awewa ati igbadun ara-eni ti won se lewo ti o jina si iduro sinsin. Onimo-jinle “Henry Makow Ph.D” so bai pe: “Dajudaju ogun geesi iwo-orun pelu awon ijo musulumi ati larubawa je ogun oselu pelu erongba ati je gaba le awon nkan oro ilu wonyi ati esin won, bakanna siso obinrin won di eniti ko ni ni itiju ati piparo aso iboju re pelu aso ihoho.
Dajudaju nini akolekan pelu obinrin ti won ba je olotito ni ipepe won fun eto re ni asiko kan pato ti won si se ailakakun re ni awon asiko miran, kilo de ti won mo bere fun awon eto re nigbati oba di iya ati awon eto re ngbati o ba dagba ni asiko to sepe oni bukata si amojuto julo.
Islam se sise daada si ladayanri nigbati o ba di ogbo ti o ti wa da bi odomode pada ni oun asunmo ati ijosin si Olohun. Eleyi je ohun ti ko si ni odo awon enia wonyi ti won pepe ominira fun obinrin ati jija fun eto re.
Kini fi nda bi esin yii eyiti o fun omo niyan ni awon eto, ti yio si san won lesan rere lori pipe awon eto naa fun awon ti won ni lodo Olohun ti yio si sun won mo iyonu re. Nje awon eto yi se fi we awon eto afi ofin ati agbara gba lowo eni tosepe ti ko ba si ofin awon eto wonyi yio di oun afeku lawujo.
* keeta ko pamo lodo awon eleyameya ninu awon elesin miran si islam ati awon musulumi. “Samuel Zwemer” olori awon ijo nasara nibi apejo-jiroro ti “Qudus” ti awon nasara ti won takoko re ni odun 1935 (onka oorun) nso bai pe,: Dajudaju pataki ipolongo-esin eleyi ti awon olutele “Mesiah” Annabi Isa nfe lodo yin lati se agbedide re ni awon ilu ti won ti ntele Anabi Muhammad kii se lati mu awon musulumi wo inu esin Mesiah, toripe nbe fun won ninu eleyi imona ati aponle, sugbon ojuse ti won fe lodo yin ni lati mu awon musulumi jade kuro ninu islam... ki won wa di eda ti ko ni ajosepo pelu Olohun... wayi o koni si asopo kan ti yio so won po mo awon iwa alaponle ti gbogbo awon ijo ngbara le ninu isemi won mo....pelu eleyi e ti si ilekun imunisin lori awon ti won nbe ni abe ikapa ijoba Islam.
Omiran tun nso ninu won bai pe ‘ Ti o ba ti rorun fun wa lati mu awon obinrin jade, tabi kapa awon obinrin, a ti de ibi ti agbero lati de...’
Nibo ni ibi ti won ngbero lati de ju fi fon ibaje ati iyepere ka lo lati le je gaba lori awon ilu ati awon ara ilu naa. Won gbero pelu awon iruju ti won nfon ka yi lati ba esin Islam ati paapa re je lawujo. Dajudaju abosi yi ati sisota yi je oun ti a kori ayafi lori esin Islam nikan. Olohun ti ola Re ga ju to so bai pe:
Itumo: (Awon Yehudi ati Nasara ko le yonu si o ayafi ti o ba tele esin won, so pe: Imona ti Olohun ni imona, atipe ti o ba fi tele ife –inu won lehin igbati ohun ti o wa ba o ninu imo ti de, ko ni si fun o lati odo Olohun alafehinti kan beni ko ni si oluranlowo fun o) Surotu Al-baqarah 120.
* Dajudaju erongba nipa pipo longo awon iruju yi lori awon eto obinrin ninu Islam ni lati mu jade kuro ninu iyi nibi siso abe re ati eye re lo si bi siso o di irinse iyepere ati siso di eto fun awon okunrin pelu siso obinrin geesi di awokose fun awon obinrin – ni iwoyesi won. ki gbogbo obinrin kookan ti nka iwe yii bere lowo lakai re, yala musulumi lobinrin tabi elomiran ti ki se musulumah- nje ipo ti awon omobinrin geesi (eebo) wa ni isin-yii ni asiko wa yii je ipo abiyi fun eya obinrin ni tabi ipo iyepere ? Onimo-ijinle “Henry Makow Ph.D” nso bai pe: “Dajudaju odomobinrin amerika nsemi ni isemi alailojuti, ilopo-mewa ninu awon okunrin ni won yio ti wole to ko to di pe yio se igbeyawo ti yio si ti safeku ibale re eleyi ti o je okan ninu awon oun abiyi fun, yio wa ti di oborogidi ati eni itanje ti ko ni nikapa lori ife, dajudaju omobinrin ni awujo amerika ri ara re gegebi okunrin ti o wa mu kuro lagbo ije iyawo-ile tabi lati je iya omo, ko je nkankan ju ohun igbadun lasan lo fun okunrin ti kii se ti ife ati rire-si (pipo si). Dajudaju jije-iya je oun idagbasoke omo-enia, oun isora kuro nibi iwa alufansa, oun ireni si daada ati ibere isemi aye tuntun, sugbon ofin atowoda agbaye ko fe irufe awon eleyi fun wa, oun to gbero niki a mo semi bi eranko, ki a si mogbe leni ti onini iyawo pelu jijiro iyawo pelu iwa agbere.
Dr. G. Lebon’ nso ninu iwe re “Olaju awon larubawa” bai pe: “Ti a ba fe mo ipo oripa Al-qur’an nipa awon obinrin yio se oranyan ki a woye si ipo won ni awon akoko idagbasoke olaju awon larubawa. Papaa oti fojuhan ninu itan ti awon olukotan pa pe nbe fun won ninu awon ipo ati ola eyi ti o wa fun awon omo-iya won ode-oni ninu awon obirin (geesi). Dajudaju awon geesi won gba lodo awon larubawa awon eko nipa esin gungun ati sisaponle obinrin.
Ti oro bari bayi, ajepe Islam lo gbe obinrin ga losi mu kuro nipo eyin lawujo, eleyi je atako si awon adiokan ti o ti fon-ka. Ti o ba woye si awon nasara ipele akoko ninu awon igba arin-gbungbun o ri pe ko si nkankan fun won ninu sise aponle awon obinrin rara, ti o ba tun si awon iwe itan asiko na, o ri ohun ti yio gbon gbogbo iseyemeji nipa alamori yi danu, oo si mo pe dajudaju awon enia asiko ofin-sise won je olulekoko mo awon obinrin ki o to di pe awon elesin kristi to ko lodo awon larubawa alamori biba won lo pelu daada......,”.
Dajudaju gbogbo enia ti o ni lakai ti adamo re se deede ti o si dara yio ko ki eto re ati iyi re o je irinse ti awon ikoko-enia yio ma fi sere, awon eniti osepe erongba won koju lati gbo bukata won lo. Bakanna ni gbogbo obinrin ti o ni lakai ti o ni adamo ti o se deede ti odara yio ko ki o je irinse tita ati rira tabi ki o je ododo ti gbogbo awon ti ngbero re yio mo gboorun ti yio wa di kangere ti won yio si gbe sonu bi won ti ngbe aso ti o ti gbo sonu.
Dajudaju awon itosona islam je oun adamo omo enia ti o si ba lakai won mu nibi nini akolekan awujo re, itosona eleyi tosepe nfe daada fun gbogbo eda. Islam je esin to nre awon olutele re lori iwa omoluabi, imototo ati inife iyi, bakanna lo je esin to nre ni ni rire to da eyito sepe lati ipase re yio mo se amojuto awujo pelu iyonda Olohun nibi siso awon ihuwa-si omo enia.
“Odomokunrin kan wa si ódó ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – o wa so pe: Iwo ojise Olohun; yonda sina (agbere) sise fun mi !!! ni awon enia ba doju bo won si jagbe mo, Ojise Olohun ba da won lake, O wa so fun odomode naa wipe: “sun mo mi” O si sun mo, o si joko. O wa so fun pe: “Se o fe eleyi fun iya re ? o ni rara mo fi Olohun ti O fi mi jin o bura, kosi eni ti o fe ninu awon enia fun iya won. Ojise Olohun tun so pe: “Nje o wa fe fun omo re obinrin bi ?” o ni rara iwo ojise Olohun mo fi Olohun ti o fi mi jin o bura, kosi eni ti o fe ninu awon enia fun awon omo won obinrin. Ojise Olohun tun so pe: “Se o wa fe fun omo-iya re obinrin ?” O ni rara, mo fi Olohun ti O fi mi jin o bura, kosi eni ti o fe ninu awon enia fun awon iya-won obinrin. Ojise Olohun tun so pe: “Se o wa fe fun aburo baba re lobinrin ?” O ni rara, mo fi Olohun ti O fi mi jin o bura, kosi eni ti o fe ninu awon enia fun awon aburo baba won lobinrin. Ojise Olohun tun so pe: “Se o wa fe fun aburo iya re lobinrin ?” O ni rara, mo fi Olohun ti O fi mi jin o bura, kosi eni ti o fe ninu awon enia fun awon aburo iya won lobinrin. Ojise Olohun wa gbowo le laya o wa so pe: “Iwo Olohun se aforijin ese re fun ki O si se afomo okan re ki O si ba so abe re” leyin igbana odomokunrin na kii boju wo nkan eewo kankan..” Al’imam Ahmod 5/256 (22265).
Ninu awon iruju, eleyi ti won nfon-ka:
1). Oro nipa nini aya pupo:
Dajuaju sise alekun iyawo fife ofin Olohun ni, ko leto fun eni ti ogba Olohun gbo ati awon Tira ti O fi ranse lati Sanmo gbo ki o se atako re tabi se igunri si. Nini iyapo pupo ninu islam sunna ni gegebi awon esin ti osiwaju re, kii se nkan ti o dawa fun Islam nikan, o je oun ti se adayanri gegebi ase so pe ofin ti o ti pe ni ti gbogbo awon esin ti o ti gbawaju si fi rinle bo ti se wa ni iwe At-taorata ati Injiila. Opolopo ninu awon Anabi –ki ola Olohun moo ba won – siwaju ki won o to gbe anabi Muhammadu dide – ki ike ati ola Olohun moo ba – je eniti mo ni awon iyawo ju eyokan lo ti ko ni odiwon. Anabi Ibrahim – ki ike ati ola moo ba- ni iyawo meji, anabi Ya’qub – ki ike ati ola maa ba – iyawo merin ni o ni, ti anabi Sulaimon – ki ola moo ba – si ni opolopo iyawo, ati be be lo. Nigbanaa ajepe alamori fi fe iyawo pupo kii se alamori kan ti oje oun tuntun bi kii se pe on ti o ti pe pelu pipe igba (asiko) ni.
O nbe ninu At-taorata: Iwe majemu lailai ninu Tira-mimo awon Yehudi nso bai pen”Won ko gbodo mu omobirin kan lati je iyale fun omo-iya re, nitori fifi I oho re han ninu isemi” Ko ko fife iyawo pupo bi kii se pe o ko fife omobirin po mo omo-iya re.
Gegebi won ti so ninu At-taorata funra-re ninu iwe samueli o wa nibe pe dajudaju Anabi Dauda – ki ike ati ola moo ba – je eni ti o ni opolopo iyawo yato si awon omo-odo re lobirin. Bakanna ni o wa lati inu iwe awon oba pe dajudaju Anabi Sulaimon – ki ike ati ola moo ba – je eni ti o ni ogorun-meje (700) iyawo ti won je omoluabi ati ogorun-meta (300) ninu awon omo-odo lobinrin.
Nigbati won gbe Musa dide – ki ola Olohun moo ba – o fi fife iyawo pupo rinle lai fi ala onka kan si fun okunrin lati fe ninu awon obirin, titi awon omo isireli fifi odiwon si fife iyawo, sugbon apakan awon aafa awon omo isireli ko fife iyawo ju eyokan ti awon apa miran si fa ra mo nitori awon okunfa are iyawo abi jije agan re (ti ko le bimo).
Al-injiil: Isa – ki ola Olohun mo ba – wa lati pe ofin Musa – ki ola Olohun mo ba – bakanna ni ko si ninu Injila oro kan to se fife iyawo pupo leewo.
Oba Arilanda (Highland) “Disamet”, iyawo meji ni o ni, ati oba “fediriki” eleekeji iyawo meji ni o ni pelu ifowosowopo soosi (ile ijosin awon Nasara), bayi ni owa han pe sise fife iyawo pupo leewo kosi si ninu esin awon Nasara (kiristani) bi kii se lati odo awon Alagba soosi.
“Martin luther” oludasile ijo “Protestantism” o ka fife iyawo pupo si eto ti ko tako awon idajo ofin mesiah, o si mo npepe si fife iyawo pupo ni gbogbo aaye
Beeni pe Olohun se ni iyonda fun awon enia kan ninu awon agba ijo iwe majemu lailai ni awon asiko isesi kan ti won sadayanri, sugbon elesin mesiah to ba fe lati kose won o leto fun lati se be nigbati o ba ti mo amodaju pe isesi re jo isesi won, dajudaju fife iyawo pupo lori eyikeyi isesi o lola ju kiko iyawo sile lo.
Dajudaju sise fife iyawo pupo leewo ninu esin Nasara wa ni abajade si awon ofin ti won gbe kale lati odo awon alagba soosi, ki si ninu ofin esin won rara, dajudaju soosi igbalode pelu idari “Baba Roma” lo se fife iyawo pupo leewo, lapejuwe:
* Ijo Orthodox ko fun ikan kan ninu oko ati iyawo lati fe elomiran nigbati fifera-eni ba si nbe.
* Ijo “Armenian orthodox” ko yigi-siso eleekeji ayafi leyin igba ti igbeyawo akoko ba tuka.
* Ijo " Greek orthodox" gba pe igbeyawo ti o duro si adina fun igbeyawo tuntun.
Awon larubawa nigba aimokan: Fife iyawo pupo je oun ti o fan ka larin awon idile larubawa ni asiko aimokan siwaju Islam lai ni onka, okunrin si mo nfe oou ti o ba wu ninu awon obirin.
Ni paapa fife iyawo pupo je oun atijo lodo awon Misira ati faranse ati awon Assyriani ati awon Jepani ati awon hindosi gegebi awon Rosia ati awon idile Jamaaniki naa se mo ti apakan awon oba Yunani(Greek) si se.
Latara eleyi yio han siwa pe fife iyawo pupo kii se alamori tuntun ninu islam, awon ijo ti o saaju ti fi sise se, nigbati islam de, o se leto sugbon pelu awon majemu ati awon aala, ninu awon majemu re:
1). Ko gbodo lekun iyawo merin, fun hadisi ti o wa pe “Gilan omo Salamo At-thaqofi gba islam ti awon obirin mewa si nbe labe ase re, ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o mo ba – si so fun pe: “Se esa merin pere ninu won” Sohihu Ibn Hiban 9/463 (4156).
2). Deede ati dogba: Botijepe dajudaju Olohun (afomo Re Oba to ga ju) se fife iyawo pupo leto be naa o se deede ati dogba ninu awon majemu re, ati jijina si abosi ati ibaje larin awon iyawo, ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun mo ba a nso bai pe: “Ti okunrin kan ba ni obirin meji ti ko wa se deede larin won, won yio mu wa lojo igbehinde ti abala egbe re kan yio ti ye” Ahmod ati Tirimisi lo mu jade.
Itumo eleyi nipe deede ati dogba nibi oun ti o so po mo awon alamori ti o nii se pelu owo nina, ebun ati awon eto inu-ile, sugbon nini fe ikan ju elomiran lo ninu awon iyawo ko si ese nibe nitoripe omo enia o ni kapa lori re, a mo kogbodo je okunfa fun nini ifasehin nibi eto awon iyawo yoku gegebi “Aisha” – ki Olohun yonu si - se fun wa niro pe: “Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o mo ba – mo nse pinpin orun larin awon obirin re ti si mo nse deede, leyin na yio wa so pe: Olohun-oba eleyi ni ipin mi nibi ohun ti mo ni ikapa, mo se bu mi nibi ohun ti O ni ikapa re ti e mi ko ni ikapa re” Sohihu Ahmod Sakiri, ninu “Umudatu Tafsiri”.
3). Nini ikapa lori ninawo fun iyawo keji ati awon omo re. Ti o ba mo amodaju pe oun ko nikapa owo nina lori iyawo keji ati awon omo re, ko leto fun lati ko iyawo jo.
O seese ki a tokasi nisoki apakan ninu awon alamori ti o je pe lopo-igba ni awujo kan ninu awon awujo kii mori bo nibe leyin ao tun woye si pe nje fife iyawo pupo se oore ni tabi aburu loje fun awujo, atipe se oore loje fun obirin tabi bee ko ?
1). Yiyagan obirin ti ko lee bimo ti oko re si nfe omo, kini eyi ti o lola ju ti o si da fun obirin ? ki o fe obirin miran le ki oun naa si mo be ni abe akata re tabi ki o ko sile lai se pe ose ese kankan, nitoripe oko ni eto gegebi oun na se ni eto nibi wiwa omo.
2) Iyawo ti aare kogbogun kolu, ti ko ni ikapa pelu eleyi lati dide si awon eto loko-laya. kini ohun ti o lola ju fun obirin na ? fife iyawo le pelu siso awon iyi re tabi kiko sile abi mimu awon ololufe aale?
3). Apakan awon okoyawo won ni agbara ijomo-enia leyi ti obirin kan ko le kawon, tabi ki asiko nkan-osu obirin ati asiko eje-ibimo re gun ju bo tiye, tabi ki o ni eya ara ti kii fi mo adun ti owa je okunfa ti ko je ko rorun fun lati gba agbatan oru ara oko re, ki ni eyi ti o lola ? se ki o fe iyawo pupo ni tabi ki o moo lo agbara yi sibi eewo ?
4). Ninu ohun ti kosi iyemeji nibe ni pe dajudaju opolopo ogun-jija ati awon isoro inu-ile ni opolopo awon awujo ni o mo nje wipe eni ti mo nforiko ju ni okunrin lai ni kan obirin. Eri to dara ju fun eleyi ni ogun agbaye alakoko ati ogun agbaye eleekeji ati eleyi ti o sekupa ohun ti ole ni ogun milionu okunrin (20,000,000). Ti okunrin kookan ba duro lori obirin kan, kini ko je iyorisi ati ipin awon obirin to seku. Se won fe fun won ki won o mo wa adun won si ona eewo ni.!! Abi ki won mo ri adun ati amuyo ife pelu ona ofin sheria ti yio mo so aponle ati iyi won fun won, ti yio si daabo bo eto won fun won, ti won yio si mo bi awon omo ti o ba ilana sheria mu ni oju-ona yiyonu si fife iyawo pupo? ninu ohun ti ko si iyemeji nibe nipe dajudaju bibe opo obirin lai ni oko yio so ona lati mo hu iwa-ibaje di irorun fun awon okunrin.
5). Bibe opolopo ninu awon opo ati awon ti won ko sile ati awon ti won ti di abileko, ki ni eyi ti o lola ju fun obirin nibi awon isesi yi ? se ki o mo be lai loko ni tabi ki o wa labi bogi okunrin ti yio mo so iyi re ti yio mo daabo bo omoluabi re pelu iyawo miran.
Nje fife iyawo pupo nbe ni awon awujo ode-oni:
Dajudaju fife iyawo pupo nbe ni gbogbo awon awujo ode-oni sugbon ni awujo ti kii se awujo Islam eleyi waye pelu pipe ni ore-aayo ati aale dipo ki won so di aya. Eleyi je oun togbajumo la won awujo yii laisi ala fun okunrin nibi onka obirin to le mu ni ale, bakanna ni ko si ofin ka pato lori irufe isesi yii. Bakanna ni pe ko je dandan fun okunrin eyikeyi ojuse owo-nina fun obirin eleyi ti nbaa lo ju kogbo bukata adun lara reti obirin yio mo wa da jerora oyun ati awon ti o niise pelu re. Bakanna ni kii tun se dandan fun okunrin lati se amojuto awon omo ti o ba jade lati ibi idapo yi. A mo nini aya pupo ni awujo islam je ohun ti o ni aala pelu iyawo merin pelu yigi ti o ba ofin sharia mu pelu si sanwo ori fun obirin, ohun ti o ba je jade ninu awon omo ti o je ere idapo larin awon mejeeji, okunrin yio mo sakolekan won gegebi awon omo re nibamu si ilana ofin Sharia, o si tun je dandan fun bakanna lati dide si nina’wo fun ati awon omo re.
O seese ki onibere kan mo bere pe: Ti a ba se nini aya pupo leto fun awon okunrin ki nii se ti a ko se leto nidakeji nini oko pupo fun awon obirin na ?
Esi ni pe; bibere fun dogba-n-dogba larin awon okunrin ati awon obirin nibi alamori fife pupo alamori kan ti ko le sele ni nibi siseda ati niti adamo:
Amo ailesele re niti siseda: toripe okunrin ni gbogbo awon awujo agbaye je eni eto jije olori ile latari jije origun ti o lagbara ju. ki a gbe awon eyi ti o sowon ninu ofin yi kale nipa riri die ninu awon obirin ti o ni agbara. Nigbati o ba nbe fun obirin oko meji tabi ju bee lo tani yio je oludari ile ? Taa ni yio te’ba fun lati mu ohun ti won nfe wa si imuse ?
Amo ni abala ádamo: Adamo obirin nipe ko lee ni oyun ju eekan lodun lo fun okunrin kan soso, yato si okunrin ti o je pe o rorun fun lati ni awon omo topo lati ara awon obirin pupo ni asiko kanna. Ti won ba se fife pupo leto fun obirin ewo ninu awon oko mejeeji ni yio se afiti omo si lodo?
Ibere apakan awon onirori iwo-oorun (geesi) fun fife pupo:
Ninu ohun ti oun ti odara ni ki a menu ba die ninu oro apakan awon onirori geesi ti won nbere fun fife ayawo pupo ti won si ri si ona kan soso lati ko di opolopo ninu awon isoro awujo won.
Onimo nipa oro siso ati lakai “Gustave Le Bon” nso ninu iwe re (olaju awon larubawa) pe: Dajudaju nini aya pupo yio ma mu awujo jina si awon egbe ati awon ewu ale yiyan ati nibi mima ri awon omo ale ti won ko ni baba.
Omidan “Annie Besant” nso ninu iwe re (awon esin ti o tan ka nilu india) pe: Emi mo nka ninu majemu lailai (At-taorata) pe dajudaju ore Olohun eleyi ti o fi emi ara re sile nibamu si erongba Olohun je eniti o ni iyawo pupo. Lafikun eleyi dajudaju majemu tuntun (Injiila) ko se fife iyawo pupo leewo ayafi lori eni ti o ba je olori awon Nasara tabi Alagba-Ijo, awon mejeeji yi ni o je dandan fun lati gba tito pelu iyawo kan, bakanna ni mo tun ri fife iyawo pupo ninu awon iwe India ijohun, won ko si mo fi pegan islam ju pe o je ohun ti o rorun fun omo-enia lati se iwadi awon alebu ti o wa ninu adiokan awon miran lati se afihan re. A mo bawo ni yio se leto fun awon geesi lati se aya-gbangba si pipo longo lati kodi fife iyawo pupo leyi ti o ni aala lodo enia ila-oorun pelu pe iwa-agbere ti je ohun ti o fanka ni ilu won ? Eniti o ba ronu jinle ko ni ri fife iyawo kan si ohun aponle enia ayafi lodo awon enia perete ninu awon eni imototo. Ko leto ki won so nipa ileto kan pe awon enia be je alaya kookan lo kurugba ti ba nbe fun awon ale leyin iganna. Nigbati a fi osuwon ti o se deede won, o han si wa pe fife iyawo pupo lona islam leyi ti yio mo se iso, aabo, pese onje, ti yio si ma daso bo awon obirin je eyi ti o tesuwon ju awon alagbere geesi eleyi ti nfun okunrin ni iyonda lati mo mu obirin ni ohun amusadun lasan lo, leyin na yio si ma juko sina mo ni ojude leyin igbati o ti jegbadun lara re tan, won wa la mole pe awon alamori mejeeji yii iwa buburu ni ! A mo won se idekun fun elesin mesia lati fi enu-abuku kan omo-iya re nibi ise ti won jo kopa ni sise re.

2). Obirin ati eri-jije:
Olohun ti ola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (Ki e si pe awon eleri meji ninu awon okunrin yin ki won jeri si i, sugbon bi e ko ba ri okunrin meji, ki e wa okunrin kan ati obirin meji ninu awon ti e fe pe ki won je eleri; bi okan ninu won ba s’ina (tabi gbagbe), okan ninu won yio ran ikeji l’eti) Surotul’baqoroh 282.
Olohun (afomo Re Oba to ga ju) nse alaye nibi aaya alaponle yi pe dajudaju jijeri nibi sisafirinle awon eto ko lee pe ayafi pelu eri okunrin meji tabi okunrin kan ati obirin meji.
Ike lati odo olohun nipe ose obirin ni oloju aanu ti o gbopon ati igbarata tole, eleyi si ni iroyin gbogi fun paapa jije enia re ki o le mo dide si awon ojuse ti o je adamo fun ninu isemi re nibi oyun nini, fifomo lomu, titoju omo ati eleyi ti o ni bukata si ni opolopo igba ni eyi ti o ni bukata si okan kan ti o lé ti o ni igbarata, akolekan ati aanu.
Ohun ipile ni pe o je alaanu nibi adamo re, aso aabo nibi awon isesi re, olé nibi riri alamori ti o seese ki o lapa lori emi re nipa awon isele ti nri ati eyi ti o rokirika awon ohun ti o sopo mo eri-jije. Deede Olohun-oba wa fe lati ni ijiro fun aileda eri je re, nitori eleyi ni won fi gbe ijeri re jina si awon alamori ti o lewu gegebi gbigbemi tabi sisani-logbe toripe wiwa re ni awon aaye isele gbomi oto gegebi pipa-enia tabi sisani-logbe kii rorun fun lopolopo igba pe ko le kemi ara re nijanu lati duro titi iwa-ese na yio fi pari leyi ti o ropo mo ilekoko, bi kii se pe yio gbiyanju lati sakuro nibe, ti ko ba ri yen se yio pada wa di oju re mejeeji nitori ki o ma ba ri ifunpinpin ti o lekoko leyi ti o seese ki o waye, iyen kosi ribe bi kii se pelu okunfa ti a ti toka si, eleyi pelu adamo nipe yio pada lapa lori eri-jije re.
Atipe pelu bi islam sese l’eto fun obirin gbogbo sisebi-otiwuni nibi dukia ti o si se gegebi ti okunrin bakan-n-kanna, sugbon adamo ati atejise talakojopo fun obirin yio maa pepe si bibe ninu ile lopolopo igba fun nitori lati maa seto inu-ile ati lati maa dide si awon ojuse molebi leyi ti ojuse yi yio gba asiko ti o po lowo obirin, leyi ti yio maa mu jina si awon aaye kara-kata leyi ti o ma nwaye nibe lopolopo igba awon gbonmisi-omi-o-to ati jija si owo. Ti o ba sele pe o lo si awon aaye gbonmisi-omi- o-to ati jija si owo yio je lilo kan ti o so won. Awon ohun ti si maa nsele nibe ninu ifanfa ati gbonmisi-omi-o-to je awon alamori kan ti ko kan rara ti ko si nii fe lati ranti re, ti won ba wa bere jijeri lowo re, yio je ohun ti o sunmo fun gbigbagbe oun to se le tabi siseyemeji re si alamori ti o sele, a mo ti obirin miran ba tun je eleri pelu re, igbagbe tabi asise ti o seese ki o waye yio ye kuro fun. Ni paapa alaye sise jijeri obirin meji ni majemu ti waye pelu oro Olohun ti ola Re ga ju ti o so bai pe:
Itumo: (bi okan ninu won ba s’ina (tabi gbagbe), okan ninu won yio ran ikeji l’eti) Surotul’baqoroh 282.
Tabi ni itumo pe: Ni iberu pe ti okan ninu won ba se asise tabi gbagbe, iranti yio wa maa be fun pelu jijeri obirin miran. Eleyi ni gbogbo ohun ti nbe ninu alamori na, kii se bi awon kan ti nlero pe o je mimu adinku ba iyi re ati iyepere, ti o ba je pe oro na ri be ni won ko ni gba eri re je nibi awon alamori ti o niise pelu awon isesi awon obirin nikan ati eleyi ti won ko le se atojubo re lopolopo igba ju awon nikan lo. Won yio gba eri re nikan je lai si eri awon miran nibe nibi sise afirinle ibale obirin, ati sisafirinle igbebi-omo, ati sisafirinle awon alebu ara obirin ati ohun ti o jo be, ti o si je pe won ko le gba eri okunrin kan je koda ko je nibi alamori oro owo ti o mo niwon. O rorun fun wa lati so ‘pe o ya kuro lara okunrin nibi dida-jeri ni oun nikan nibi awon ohun ti o lewu ninu awon alamori ju owo lo, alamori na je alamori kan ti n pepe lati ni amodaju nibi awon idajo.
Bee na ni ‘pe won ko ni gba eri okunrin ni oun nikan je nibi awon alamori oro owo bi kii se pe agbodo ri eri okunrin miran pelu re titi ti ododo yio fi f’ese rinle, eni kankan ko woye si pe gbigbe iyi fun eri okunrin pelu eri okunrin miran pelu re je iyepere fun aponle re ati mimu adinku ba a.
Bakanna won yio tun se afikun iyen pe dajudaju jijeri kii se iwo kan ninu awon iwo ti awon enia yio ma difun-n-fun le lori, bi kii se pe o je eru kan ti o wuwo ti awon enia ma n sa fun u, nitori re ni Olohun (afomo Re oba ti ola Re ga ju) fi pa l’ase mi momo sa fun eri jije, Olohun ti ola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (ki awon eleri ma si se ko (lati jeri) nigbati won ba pe nwon) Surotu al-baqoroh 282.
Ibanisoro yi je ohun ti o kari okunrin ati obirin, ti a ba ti wa mo pe eri-jije eru kan ti o wuwo ni ti awon omo-enia ma nsa fun nitori ohun ti o sopo mo ninu awon inira ati ohun ti o wa nibe nibi pipe ni si awon ibujoko idajo ti o seese ki o pe, ati ohun ti o le sopo mo ninu wahala ara ati owo ni na.
Islam nibi bibu-oju anu wo obirin fi gbiyanju lati se idekun fun nibi awon erú inu isemi aaye nigbogbo ona, koda o tun pa apakan awon erú gbigbe fun u, gegebi mimu’le ro ati ojuse owo nina lori ebi ti yio fi le raye fun awon ojuse Pataki ti won so mo lorun. Eleyi je aponle fun obirin kii se didin eto re ku rara.
Ni afikun leekan si; dajudaju sheria islam se eri re ni idakeji fun eri okunrin ati ibase deede re nibi sise atako eri jije nibi isebile nigbati oko re ba le oko-sina mo ti ko si ni ohun ti o le f’ese ododo mule, Olohun ti ola Re ga ju lo so bai pe:
Itumo: (Ati awon eniti nwon npe (pansaga) mo awon aya won ti ko si awon eleri fun nwon ayafi awon funra won, eri eni kookakn won ni ki o fi Olohun jeri lemerin pe dajudaju o un wa ninu awon olododo. (6) Atip ekarun ni pe ki ibi Olohun maa be lori o un bi o ba je okan ninu awon opuro. (7) Nigbana a o tari iya kuro fun o un (obirin) ti o ba fi Olohun jeri lemerin, pe dajudaju o un (oko) je okan ninu awon opuro. (8) Elekarun ni pe ki ibinu Olohun maa be lori o un (obirin) bi o un (okunrin) ba mbe ninu awon olododo. (9).) Surotu An-nuur 6-9.

3). Didide si ojuse-eni:
Olohun ti ola Re ga ju so bai pe:
Itumo: (Awon okunrin ni opo-mulero fun awon obirin nitoripe Olohun se ajulo fun apakan won ju apakan lo ati nitori ohun ti nwon nna ninu dukia won) surotu An-nisai 34.
Opomulero je ohun ti won mu latara didide si nkan, osi je oun adanyanri fun awon okunrin nikan yato si awon obirin, nitoripe okun-ara ati lakai ti nbe fun awon okunrin fun won ni anfani lati dide si eto opomulero. Ohun adamo ni ati ni asiko kanna ni o tun je oun ise nitori ohun ti won se loranyan lori awon okunrin nibi didide si eto obirin nibi nina’wo fun ati didide si awon ojuse re nibi didaabo bo ati sise amojuto re ati pipese awon nkan isemi fun, adaranje ni (okunrin) ninu ile re won yio si bi leere nipa did’eranje re lowo re gegebi ojise Olohun Muhammadu – ki ike ati ola Olohun maa ba a – se fun wa niro re.
Amo obirin ni abala okun-ara o je eni ti o le nitori awon aseriwa t’opo ti i ma nseri waa ba ninu nkan-osu, oyun nini, omo-bibi, fif’omo-loyan ati titoju omo, ko le ni ikapa ni ntopoju pelu oun ta sosaju yii lati dide si eto opomulero l’ojuponna ti o pe ju.
Nkan-osu: O ni oripa lori emi ati ara obirin, bakanna ni o ma nkole ba ara re nitori ohun ti nsafeku re ninu eje ni gbogbo osu.
Oyun: Obirin ma nri nkan t’opo nibe gegebi inira ara pelu didagba-soke ole-inu ati fifa eyi topo ninu ounje re ti yio wa ko aare be, eyikeyi iwon ba igbiyanju yio ma lapa lara re tabi ninu emi re pelu okunfa iberu lori omo re ati fifoya lori re ati pipaya ohun ti o le sele si lasiko bibi re ninu ohun ti o ma ni ilapa buburu lori emi re, bakanna si ni yio se ayipada iwa ati awon isesi re.
Bibi-omo ati ohun ti mbe lehin re: ati awon ohun ti o ropo mo ninu awon inira ti o lekoko ti yio ma pepe fun lati ni isinmi ara re lai ni se igbiyanju kankan tabi wahala kankan fun emi ara re fun asiko die ninu igba ti iyato si wa nibe pelu iyato awon obirin si’ra won.
Fifun-l’omu: Dajudaju fifun obirin l’omo re l’omu o nii se pelu re pe ipin kan ninu ounje re yio ma lo si odo omo re, eleyi je ohun ti ko si iyemeji nibe ninu ohun ti ma nlapa lori alafia re, lofaa ti ofi ri apakan awon obirin ni asiko fif’omo l’omu ti irun ori re yio ma re tabi ki awo re o maa si tabi ki o ma mo l’ara efori apakan, oju-pipooyi ati riru (gbigbe).
Titoju-omo: Titoju-omo ati ohun ti o sopo mo ninu aisun sise ati dide si awon ojuse omo yio ma gba eyi t’opo ninu asiko re.
“Al-Aqod” so bai pe: Dajudaju obirin ni isesi aanu adani ti ko jo isesi okunrin, nitoripe didun ni mo omo npepe si opolopo nkan ninu ajosepo larin riropo iya omo ati baba ati larin agboye iya ati baba, eleyi si ni ipile okan obirin eleyi tii ma nso obirin di oluyara ju’wo sile fun igbarata ati didahun ipepe-aanu, yio wa nira fun ohun ti o rorun fun okunrin nibi lilo lakai ati irori ti o ga ju ati ipin-nu to gbopon.
Bee ni ojogbo “Dr.Alexis Kirill” na nso nigbati nsalaye iyato eya-ara larin okunrin ati obirin: Dajudaju awon alamori tii ma nse opinya larin okunrin ati obirin kii se nibi jijina si ara won nikan nibi aworan eda pelu awon eya-ara r ati apoluke (ile-omo) ati oyun, bakanna ni kii se nibi yiyato awon ona ikeko (obirin), bi kisepe dajudaju iyato arin won je iyato nibi adamo ti ipile, nibi iyato eya iseda ninu ara awon mejeeji ati nibi gbogbo akojo ara nibi awon irinse kan ti o ti wa ni sepe ti eya inu-ara yio pin si oririsi aaye, bi o ti se jepe obirin yato si okunrin patapata nibi awon irinse ti o wa ninu ara tii ma nkojo nibi apoluke (ile-omo) ninu ara obirin. Awon ti won pepe deede eya ti o le (obirin) pelu okunrin won je alaimokan si awon opinya ipile yi, won npariwo pe ko gbodo mo ma be fun awon mejeeji iran kanna nibi eko, ojuse ati awon ise-oojo, amo obirin nipaapa amodaju yato si okunrin gedegede, gbogbo eya kookan ninu ara re loni adamo jije abo, bee na si ni awon orikerike ara re. Be naa nipe agbara okunrin le ju agbara obirin lo, eleyi je ohun ti o han gbangba. Awon okunrin mo ndide si awon ise ti o le ti o si nira lati se, ti obirin si ma nkangara lopolopo igba lati dide si.Pelu ohun ti o ti gbawaju yio ti han yekeyeke idi ti okunrin fi l’eto lati je opomulero fun obirin.

4). Eto obirin nibi ogun-jije:
Islam de o si fun obirin ni eto re nibi ogún leyin ti o ti je pe kosi eto fun nibe nigbati o je pe eto awon okunrin ni ogún je toripe awon ni won ma ndaabo bo ebi ti won si ma ndabobo kuro lowo awon ota, ko mo lori eleyi nikan ni, amo nse ni won ma nje m’ogun bi won ti ma njogun nkan-oro. Lati odo “Ibnu Abbas” – ki Olohun o yonu si – nibi oro Olohun tola Re ga to so bai pe:
Itumo: (Enyin onigbagbo ododo, ko to fun nyin lati supo obirin ni tulasi, Beeni e ko gbodo de won mole ki e le gbon apakan ohun ti e fun nwon danu) Surotu An-nisai 19. O so pe: “won je eni ti o je pe ti okunrin ba ti ku, awon enia re ni won je eni ti o leto si obirin re ju, ti o ba hu apakan won o le fe, ti o ba si hu won, won le fe fun elomiran, ti o ba si tun hu won won le ma fe fun enikeni, awon ni won leto si ju awon enia re lo, aaya yi wa so kale lati kodi iru isesi yii.” Sohihu al’bukhori 4/1670 (4303).
Islam ba de o si se eleyi ni eewo, Olohun ti ol Re ga ju nso bai pe:
Itumo: (Enyin onigbagbo ododo, ko to fun nyin lati supo obirin ni tulasi, Beeni e ko gbodo de won mole ki e le gbon apakan ohun ti e fun nwon danu) Surotu An-nisai 19.
O si fun ni eto re ninu ogun, o si pin ohun ti o pin fun, Olohun ti ola Re ga ju lo nso bai pe:
Itumo: (Awon okunrin ni ipin ninu ohun ti awon obi ati ibatan (won) ba fi sile (ku), obirin na ni ipin ninu ohun ti awon obi tabi ibatan (won) ba fi sile (ku) ninu eyi ti o kere tabi opo re, ipin ti a ti pinnu re ni.) Surotu An-nisai 7.
“Seyyidul’qutub” – ki Olohun ti ola Re ga ju ki O se ike fun – nso bai nibi itumo aaya yi,: Eleyi ni ipile apaapo ni eyi ti islam fun awon obirin lati ogorun odun merinla (14 C.E) eto ogun-jije gegebi okunrin, bi o tun se so awon eto ti nbe fun awon omode ti igba aimokan ma nse abosi won, ti sii ma nje awon eto won, toripe igba aimokan ma nwoye si okookan ninu awon enia nibamu si pataki won niti ise l’oju ogun ati imujade (éré), amo islam wa pelu oju-ona re lati odo Olohun wa ti nwoye si omo-enia nibamu si pataki omo-enia re, ti eleyi si ohun pataki ti ko le ya omo-enia leyi isesi (ipo) kan ninu awon isesi re, lehin na o tun woye si nibamu si ilaborun re larin ebi ati l’arin awujo.
Olohun tola Re ga ju lo nso bai pe:
Itumo: (Olohun pase fun nyin nipa (ogun) awon omo nyin; okunrin yio maa ni ipin obirin meji) Surotu an-nisai 11.
O seese ki o bo sinu lakai eni ti oye islam ko ba ye nigbati o ba nka aaya yi ‘pe o din eto obirin ku, bawo ni yio ti maa be fun obirin idaji ohun ti nbe fun okunrin ninu ogun ?!
Olohun (afomo Re Oba tola re ga ju lo) ti salaye ogun obirin ni alaye ti o pe, O si fi ogun re sibi awon isesi meta:
- Ipin re nibi ogun gegebi ipin okunrin.
- Ipin re nibi ogun gegebi ipin okunrin tabi ki okere si.
- Ipin re yio je idaji ipin okunrin nibi ogun, eleyi si ni o bori ju.
* O seese ki eni ti o ba fe mo alekun lori akori yi ki o seri lo sibi awon iwe nipa imo ogun-pinpin eleyi ti o salaye nipa akori na ni alaye ti okun rere.
Ki a to se idajo lori islam lori pe nje o din eto obirin ku nibi ogun lotito tabi ko dinku, ki a mu apejuwe kan wa ti ogbon ti nbe nibi sise ogun obirin ni idaji ogun okunrin yio latara re; okunrin kan ku fun omokunrin ati omobirin kan, o si fi odiwon kan ninu dukia sile lapejuwe bi egberun-meta riyal owo saudi (SR 3,000) eto omokunrin nigbati won ba pin yio je egberun-meji (2,000) ti ipin obirin yio si je egberun-kan (1,000).
Ki a wa woye si ipo owo yi leyin asiko die nibamu si okunrin ati nibamu si obirin, nibamu si okunrin; dajudaju owo ti o jogun yi yio dinku nitoripe o s’oranyan fun lati san owo-fife (sadaki) fun iyawo ti yio fe, o si s’oranyan fun lati pese ile ati lati duro fun awon eto inu-ile ati itoju enikookan ninu ebi ati nina’wo lori gbogbo okookan ninu iyawo ati awon omo ati diduro fun ohun ti won nbere fun, kii se iyawo ni won yio bere lowo re lati dide si eyikeyi nkankan nibi owo nina ati awon eto inu-ile, koda ko je olowo, bi o tun se je pe o s’oranyan le lori (okunrin) ninanwo fun awon obi re mejeeji ati awon omo iya re ati awon alasunmo re ti ninawo je dandan fun lori won nigbati won ba je alaini tabi eni ti o le ti oun si ni ikapa.
Amo nibamu si obirin; eni abiyi ni, eni aponle ni oun, eni ti ife, amojuto ati ninanwo fun bo daru ni, ti won ko ni bere lowo re gbigbe owo nina ru, ti ko si je oranyan fun bakanna koda koje ninawo fun emi ara re. Nigbana a je pe owo ti o (obirin) jogun re yio ma lekun ni ko ni dinku nitoripe yio tun pada gba owo-fife (sadaki) lowo oko re nigbati o ba fe, koda ko je pe opinya sele larin oko ati aya re, dajudaju o soranyan fun oko nibamu si sheria lati maa nanwo fun awon omo re ati lati duro fun awon ohun ti won nbere fun, koda o (obirin) tun le maa fowo re se idokowo ti yio si maa mu idagbasoke ba a nibi fifi s’ówó tabi ohun ti o jo be ninu awon ona riri-ere.
Yio ye wa ninu ohun ti o ti gbawaju yio ma seku ni isinpa fun obirin nibi sisafeku molebi re, amo eyi ti okunrin ba gba ipese loje fun itore ati nina latara awon eru ti o wuwo ti ojoko le l’ọrun.
Dajuaju ofin sheria islam yato si awon ofin ti o ku ni agbaye, eleyi ti baba le y’owo kuro nibi alamori omo re obirin ni igbati o ba dagba debikan ninu ojo ori nipato ti yio je oranyan fun lati wa ohun ti yio fi s’emi pelu orisirisi awon ona ati awon okunfa. Omo-obirin ninu islam oranyan ni fun baba re ni ilana sheria lati se amojuto re titi yio fi loko, leyin yio di oranyan fun oko re lati pese fun gbogbo awon ohun ti yio ma bere ati awon bukata re leyin yio tun je oranyan fun awon omo re.
Dajudaju awon ofin ti nse ifiga-gbaga larin okunrin ati obirin nibi ogún, won tun nse ifiga-gbaga bakanna nibi gbigbe bukata ati awon ojuse owo nina ni bakan-n-kan-na. Amo bibere fifun obirin ni deede eto okunrin nibi ogún laimo bere lowo re lati gbe awon owo nina gegebi okunrin niti bakan-na kii se deede ati pipe eto, nitori abosi ti nbe nibe fun okunrin ti sheria islam ko si yonu si.
Nigbana, a je pe ninu deede ati pipe eto nibi gbigbola fun okunrin lori obirin nibi ogún nipe ki afagile gbigbe wahala owo nina kuro lori obirin gegebi ninanwo lori ile ati awon omo ati eyi ti o jo be e, koda a ri amojukuro islam ati aponle re fun obirin nigbati o se amojukuro fun nibi gbogbo awon oranyan owo nina ti o si laa bo okunrin l’orun pelu be ko ko fun (obirin) nibi ogún jije bi kii se pe o fun u ni idaji ohun ti o fun okunrin, se eleyi kii se deede ati pipe eto bi?
Ninu ohun ti o l’eto ki a safihan re ni pe dajudaju gbogbo enia kookan l’okunrin ni tabi l’obirn ni o ni ipin re ninu ogún ti ko rorun fun eni kankan lati ko fun u nibe, nitori eleyi ni won fifi aala si asoole leyi iku ninu islam pelu idameta dukia (1/3) tabi eyi ti o ba kere si ti ko fi ni si aaye fun kiko fun awon olujogun ninu ohun ti eni ti yio fun won l’ogún je fi sile, ti ko si ni ko inira ba won. Lati odo “Amir omo Sa’d omo Abi-waqos” lati odo baba re – ki Olohun o yonu si – o so pe: “Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nbe ni eni ti mo nse abewo mi ni odun Hajji idagbere latara aisan tole ti o kolu-mi, mo wa so pe: Aisan yi ti de gongori emi mi, mo si je eni ti o ni dukia, kosi si eni ti yio jogun mi ayafi omobirin kan soso, nje mo le fi idameji ninu idameta (2/3)owo mi se sara bi ? Ojise Olohun si so pe: “rara” mo ni: Pelu idaji (1/2) nko ? O ni: “rara” lehin na mo ni: pelu idata (1/3) nko ? O ni: “rara” lehin na o wa so pe: “Ida-meta ! ida-meta gan po, ki o fi awon ti yio jogun re le ni oloro loore fun o ju ki o fi won sile ni olosi ti won yio wa maa toro lowo awon enia lo, dajudaju o ko nii na nina kan niti wiwa ojuure Olohun pelu re ayafi ki won o san o lesan pelu re koda ti o fi mo ohun ti o ba fi si enu obirin re.” Sohihu Al’bukhori 1/435 (1233).
Ojise Olohun alaponle – ki ike ati ola Olohun o maa ba a –so pelu awon itosona ati awon ase re yi fun obirin awon eto re, eyi ti yio pe isemi ti o dara fun u.
Ki a tun se afikun leekan si pe owo emi ti won seesi pa – tii se diya – ati opolopo awon ilaborun ti o je ti owo ti o je jade nibi awon isele sisani-logbe je ilaborun fun okunrin nikan lai si awon obirin nibe.

5). Owo-itanran (Diya):
Ninu sheria islam owo-oran obirin idaji owo-oran okunrin ni iyen nibi isesi kan soso; ohun ni nibi isesi pipa lona asise eleyi ti o je pe owo-itanran je oranyan nibe ti ko si de ipo gbigbesan, amo ni ibamu si mimo-mo pa enia ohun ni eyi ti o so gbigbesan di oranyan lara apaayan – ti awon enia eni ti won pa ko ba juwo sile nibi eto won– dajudaju idajo eleyi koju eyokan lo nibamu si okunrin ati obirin yala eni ti o pa enia je okunrin ni tabi obirin, tabi eni ti won pa je okunrin tabi obirin nitoripe awon mejeeji ni abala jije-enia bakanna ni won.
Amo ni ibamu si pipa lona-asise eyi ti owo-itanran je oranyan nibe, o seese ki o je pe jije owo-itanran obirin ni ilaji si owo-itanran okurin nseri lo sibi odiwon inira ti yio kan molebi latara pipa okunrin tabi obirin. Atipe idile ti won pa baba won lona asise yio padanu alamojuto won ati olunanwo lewon lori ati oluduro fun awon ohun ti won nfe ati olugbo bukata won, won yio padanu abala oro-afojori ti o ko jij’emolebi sinu ati igbarata fun-ni pelu idaabo-bo ati abala oro-aifojuri tii se apejuwe fun aanu ati ike sugbon aanu ati ike re kere lopolopo si ti iya.
Amo molebi ti won pa iya won ni ti asise yio padanu iya ni abala iwulo aifojuri nikan ni eyi ti nse apejuwe fun aanu, ike, ibukun, amojuto ati ohun to jo awon eleyi ninu awon oun to niise pelu obirin ati eyi ti opolopo awon okunrin ko ni ikapa lati dide si, eleyi ni abala iwulo aifojuri, ti won ba san owo ti ko lonka fun u, kole jiro re.
Owo-itanran ninu itumo re gangan kii se odiwon eni ti won pa, amo o je osuwon fun odiwon inira ti o de ba awon molebi re, ti a ba wa mo awon inira ti o de ba awon idile na pelu okunfa pipadanu baba tabi pipadanu iya yio han si wa abala kan ninu awon abala ti owo-itanran obirin fi je idaji owo-itanarn ti okunrin.

6). Isé obirin:
Dajudaju Olohun s’eda omo-enia latara ako ati abo, O si fi si arin awon mejeeji ife ati ike eyiti osepe latara re ni ibalo pelu daada yio fi be ninu isemi aye. Gegebi Olohun (afomo re Oba tola Re ga ju) se sa okunrin lesa pelu agbara ati ikapa lori nini agbamora ohun ti yio so o di eni ti yio maa sise lori ile nitori ati-ni akojo, Olohun (afomo Re Oba ti ola Re ga ju) sa obirin naa lesa pelu ohun ti yio so gbigbara duro fun oyun, bibimo, fifun lomu ati tito di irorun, ati ohun ti yio so iyen di irorun ninu aanu, nini’fe, ike, ifarabale ati idekun. Nibamu si siseda Olohun yii, yio je pe ipó adamo fun okunrin ni jijade kuro ni'le lati loo sise latiri oun ije fun awon arale re, ti ipó adamo fun obirin si je sise ise inu ile.
Dajudaju islam ko ko fun obirin lati se ise ati lati kopa nibi tita’ja ati lilo-bibo fun isowo ati lati kopa nibi tita ati rira o si se titakoko awon nkan wonyi leto fun lai si ifowosi alaabo tabi oko nibe, sugbon o fi eto si, o si fi aala si pelu, o wa gbe awon onde ati awon majemu kale fun ti o je pe ti okan ninu awon onde yi ba kuna tabi ti won ba se afeku okan ninu awon majemu yii, iyonda re yio yipada kuro nibi lileto bo sibi kiko-fun, ninu awon majemu yi ni:
1). Dandan nipe ko gbodo si itako larin ise obirin ati ise inu-ile, ni eyi ti o je pe ise na ko je okunfa aseeto re nibi pipe awon eto ti o je oranyan lori re fun oko ati awon omo re, kosi gbodo pa amojuto ile re sofo, nitoripe obirin ninu islam gegebi o ti siwaju, o ni awon eto lori oko re bee na si oko re ni awon eto kan lori tire naa, gegebi o ti je pe awon omo re na ni awon eto lori re (obirin). Ojise Olohun ki ike ati ola Olohun o maa ba a – nso bai pe: “Atipe obirin na adaranje ni ninu ile oko re yio si bi leere nipa didaranje re..” Sohihu Al-bukhari 1/304 (853).
Osi gbodo je pe ise re pelu awon omobirin bi tire ni, osi gbodo jina tefe-tefe si idapo mo awon okunrin ati idifun-fun-n-fun pelu won nitori ati so ati lati gbe jina si ohun ti o le se okunfa ki won o maa lo sibi oun ti kodara ati lati ko lu ati lati doti omoluabi re ati iyi re awon awon ikoko-eda enia. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a – nso bai pe: “Enikeni ninu yin ko gbodo moo dawa pelu obirin, nitoripe esu ni yio se eeketa awon mejeeji.” Sohihu sunani Ibnu majah 2363.
Obirin oyinbo kan (Lady Coke) nso bai ninu iwe-iroyin (Hecko) pe: Dajudaju dida obirin po mo okunrin, ti awon okunrin naa si ti ba saba, nitori eyi ni obirin fi nrankan si ohun ti ntako adamo re, lori odiwon opolopo idapo yi ni awon omo agbere (sina) yio fi maa po si, ti adanwo totobi si wa latara isesi yii.
“Sheyyidu qutub” – kiOlohun O ke – nso bai pe,: Dajudaju ninu eto awon okunrin bi o se je pe o wa ninu eto awon obirin ni ki okookan won o ni ifokanbale si odo amugbalegbe re ki o si ji naa si awon oun ti o le yi kuro nibi igbarata fun ikeji re, ti yiyese yi ko ba mu lo sibi isubu ati asise ninu ohun ti o le ba asopo ti o mo kanga je ti yio si gbe kuro ni agbegbe ifokantan ti o pe ati igbarale, yiyese yi nibi ifara-rora ati sisubu sibi ohun ti sisele re lojoojumo jina ati nigbogbo iseju ni awon awujo eyi ti o je pe idapo okunrin ati obirin nsele nibe, ti obirin ti ose oso rin ni ihoho ti awon setani oni fitina oni-tanje si nrin pelu re, oro ti ko nitumo ti subu, eyi ti ohun to nsele gan pe ni’ro ti ahon awon eye-olofofo npara re nihin ati ahon awon ofonu npara lohun nibi wipe idapo okunrin ati obirin yio se atunse orikerike-ara yio si ji awon agbara ti won ti de mo’le yio si ko awon eya mejeeji ni awon eko tuntun ati awon eko bi enia se le mo nkan ninu ara yio si je ki won o ni oye ohun ti o ma nso enia kuro nibi asise ati sisesa – sisesa okan ninu awon oko abi iyawo– leyi ti o duro lori nini ooye ti o pe. Emi nso pe iro ti ohun ti nsele kodanu ni, wiwaye awon ese-yiye ni gbogbo-gba ati awon iyipada gbogbo-asiko nibi sisunmora ati biba awon ile je pelu kiko-sile ati aikosile ati fifonka awon ijanba ati etan loko-laya lodo ni awon awujo wonyi. Amo adapa-iro atunse ati gbigbon-idoti nu pelu pipade ati biba-soro ki won bi won lere nipa re; odiwon awon omo akeko obirin ipele keji (sekondiri) amerika ti won ti l’oyun ni okan ninu awon ile-eko won o ti to ipanna meji-din-laadota ninu ogorun (48%), amo awon idile alayo leyin igbeyawo aladalu to yanju pelu esa ti o pe, ki won bi won bere nipa re; odiwon awon ile ti won ti so agbeele won nu pelu kikosile ni amerika nma pele si ni lasiko kan si asiko kan, ni gbogbo igba ti alupo ba ti nlekun si ati ni gbogbo igba ti sise asayan ba ti nwa.
2). Ki ipile ise na o je eyi ti o leto, ki o si je eyi ti yio nibamu si adamo obirin, ko gbodo se ise ti ko ba adamo naa mu gegebi sise ise agbara ati awon ise ologun ati awon ise ti iyepere nbe nibe gegebi awon ise kole-kodoti ti o je adayanri fun awon okunrin ati gbigba oju-ona ninu ohun ti sharia islam ko o fun obirin.
Amo nibiyi ibere ma ntowa wa pe kilode ti obirin fi nsise?
Ti o ba se pe o nsise lati fi maa semi ati lati maa nawo fun emi ara re nikan, Islam ti pese eto eleyi fun, dajudaju ofin owo nina ninu islam je dandan fun baba lati maa nawo lori omo re obirin titi yio fi loko, ti o ba si ti loko owoona re ati ta won omo re ti di oranyan lori oko re, ti oko re ba ku ninawo lori re yio pada si odo baba re, ti ko ba ni baba yio bo si ori awon omo re, ti awon omo re ba kere yio bo si ori awon omo-iya re, lehinna awon molebi pelu bi won ba se sunmo mo, lati igba bibi titi di ojo iku re ni itoju yio wa fun, kosi bukata fun u lati maa sise nitori atijeun ati lati semi, iyen ko je nkan kan bi kii se lati lo asiko fun pipe ojuse re ti o ga ju ni awujo ati eyi ti won le ma pegan re le lori ati lati maa seto inu ile ati rire awon omo ni rire ti o dara, leyi ti nfe lowo re; igbiyanju ati wahala nla ti o seese ki o gba eyi ti o poju ninu asiko re ati irori re.
Onimo ede oyinbo kan “Samueli Smiles” ti o je okan ninu awon origun idagbasoke ede oyinbo nso bai p: Dajudaju eto to niise nipa sisise obirin ni awon ile-ise, boti wu ki oro maa jade nibe fun ilu to dajudaju abajade re yio wo opo isemi inu-ile, nitoripe yio je olukolu eto ile, yio si fo awon origun idile na, yio si awon okun ti o so awujo po, boti je pe oun gba iyawo kuro lowo oko re ati awon omo kuro lowo alasunmo won, be naa lo jepe ko si ayorisi kankan fun ju yiyepere awon iwa obirin lo, nigbati o je pe pataki ise obirin ni didide si awon ojuse inu-ile gegebi tito ile ati rire awon omo ati esuna nibi awon ohun amusemi, pelu didide si awon ohun ti won ni bukata si ninu ile, amo awon ile-ise yio jagba kuro lowo re awon ojuse won yi ni igba ti o je pe awon ti di ohun ti kii se ise re le lori, ti ile owa je ile mo, ti awon omo wa di o nti won ndagba lai ni eko mo, ti won oun agbe ju sile, ti ina ife loko-laya wa nku, ti obirin si kuro ni jije iyawo oludamoran ati alasunmo ololufe fun oko re ti o wa di alabarin re nibi ise ati sise wahala, o wa di ohun ti pe yio wole pelu awon oripa eleyi ti yio ma begi di iteriba ti o ba lakai mu ati awon iwa eleyi ti o je pe ohun ni akoso amojuto aponle nbe lori re.

7). Gbigbe agbara kiko-sile si owo okunrin laisi owo obirin nibe
Kiko-sile je nigba aimokan ohun ti ko ni oun ide ati eto, okunrin le ko iyawo re ni asiko ti o ba wu, o si le seri pada si odo iyawo re ni igba ti o ba wu. Islam wa wa pelu awon eto lati so awon obirin kuro lowo abosi ati iyepere ti nsele si won. Awon enia ni asiko aimokan ti okunrin si leko iyawo re ni iye igbati o ba fe, yio si tun maa je iyawo re nigbati o ba gba pada lasiko alada, koda ko ko sile ni iponna ogorun tabi ju bee lo, ti okunrin kan fi nso fun iyawo re pe: Mo fi Olohun bura nko ni ko o sile ti o fi kuro lodo mi loo fe oko miran, nko si ni gba o pada lai lai, obirin na wa so pe: Iru kini eleyi ? O so pe: Maa ko o sile, gbogbo igba ti alada re ba si ti sunmo ki o pari maa tun gba o pada, ni Al-quran alaponle ba so kale ti nso bai pe:
ItumoIko-sile eemeji ni, e mu won dani pelu dada tabi ki e fi won sile pelu dada) Surotu Al-baqaroh 229.
Paapa islam ti se kiko-sile ni eto lasiko ini bukata si ati inira isemi ati ni awon asiko ti isemi ko le duro deede ayafi pelu re.
Sharia islam nsise lati se atunse si awon ifanfa loko-laya ti kiko-sile ma ba moo waye, Olohun ti ola Re ga ju nso bai pe:
Itumo: (Bi obirin kan ba beru ilokulo lati odo oko re tabi iseri-ipati, ko si ibawi fun awon mejeeji bi nwon ba le se atunse larin won. Atunse ni o si dara julo.) Surotu An-nisai 128.
Kilode ti kiko-sile fi wa l’owo okunrin ? Nibamu si adamo ati lakai ni pe ki kiko-sile o wa lowo okunrin laise obirin nitori awon ilaborun to wa fun nibi owo nina lori iyawo ati ilu-ile, lokuru-igba ti o ba ti je pe o un ni o san owo-ife (sadaki) ti o si gbe inawo eto igbeyawo ti o si pese ileegbe, ti ninawo si je oranyan lori re, a je pe ninu eto re ni ofin fifagile isemi loko-laya ti o ba ti ni igbaradi lati gbe sisafeku-owo ati oun ti yio je jade nibi kiko-sile, nitoripe o ni amodaju pelu ohun ti kiko-sile dale lori nibi sisafeku-owo, pipadanu owo-ife eleyi ti o san ati pipofo ohun ti o naa fun awon ipese, atipe nibi ijiro ohun ti yio pada san fun iyawo leyin kiko-sile ati ohun ti igbeyawo tuntun kosinu ninu owo-nina ati awon ohun ti yio te le.
Ni afikun leekan si dajudaju okunrin ni eniti oni ikapa lati korare ni ijanu kuro nibi ibinu re ati lati je gaba lori okan re lasiko ifanfa ati aigbora-eniye ba nsele larin re ati iyawo re. Okunrin ni opolopo igba kii seri lo sibi kiko-sile gegebi atunse ikahin ayafi nigbati o ba jakan kuro nibi bibe idunnu loko-laya pelu iyawo re.
Pelu eleyi, Sharia islam ko se leewo fun obirin, o nbe fun obirin eto kiko-sile nigba ti o se e ni majemu ni asiko itakoko yigi lori oko re, ti oko na si yonu si. Sharia Islam ofin adamo ni, o nimo niti mimo ti o pe nipa omo-enia bi o ti fun okunrin ni eto sise-opinya si iyawo re nigbati ikorira re ba sele pelu kiko-sile, bakanna ni o fun obirin naa ni eto yii nigba ikorira re si oko re, nigbati o ba nsoro buburu si tabi fi’ya je, tabi ri alebu lara re (oko) gegebi ki o kagara lati sunmo obirin, tabi ki aisan ti o lewu kolu leyin igbeyawo gegebi ogodo tabi ete tabi ropa-rose tabi airomobi tabi eyi ti o yato si ninu awon aisan arisa, ti obirin wa di eni ti inira nkan, nigbana o ni eto lati bere fun titu igbeyawo ka pelu ona miran ti a mo si “yiyonda” (Khul’u), eleyi ni ijiro kan ti iyawo yio san fun oko nitori ohun ti o ti ona ninu owo-ife ati awon ilaborun igbeyawo, ifenuko yio waye lori re larin awon mejeeji, eleyi ni opin deede nigbati o je pe oun (obirin) ni obere fun itu asopo loko-laya sile, ti o ba wa sele pe oko ko lati fara mo itusile naa, o (obirin) leto lati gbe alamori re lo si ile-ejo lati fun ni eto yi.

8). Aibadogba obirin pelu okunrin nibi titakoko yigi igbeyawo:
Dajudaju ise asayan okunrin fun obirin gidi ise kan pataki ni ti o si soro gan, eyi ti o soro ju nibe ni sisesa oko ti o da fun obirin, nitoripe okunrin nigbati o ba fe obirin ti ko ba tire mu o nikapa lati fi omiran jiro re pelu irorun, atipe obirin bi a ti so siwaju pe o un ni abala ti o le ni gbogbo awujo omo-enia, islam ni akolekan pelu sise amojuto re ati didabo bo nibi gbogbo suta, o wa pase pelu sise jeje ati pelepele nibi sisesa oko ti o bojumu fun, nitori ki o ma ba je eniti yio f’ori ko aburu igbeyawo, ti yio si je oun ni eni ti yio ri inira ti o tobi ju nibe, nitori eleyi ni islam fi see ninu majemu igbeyawo ti o dara ni ki a ri aayo (alamojuto) tabi eni ti yio je asoju re ti yigi ko si ni so ayafi pelu re, fun oro re – ojise Olohun- ki ike ati ola Olhun o maa ba – ti o so bai pe: “Yigi o le so laisi alase (waliyu) ati eleri ti o duro deede meji, igbeyawo ti won ba se lona ti o yato si eleyi je igbeyawo ti ko dara, ti won ba wa yapa larin ara won, alase-ilu ni yio je alase fun eni ti ko ni alase.” Sohihu Ibn hibban 9/386 (4075).
Gegebi o ti je pe sharia se riri alase ninu ohun ti igbeyawo fi ndara gegebe naa lo tun se ninu didara re ni ki obirin oyonu si okunrin ki o si yonda fun alase re lati pe so iyigi, ti o ba lo sele pe obirin ko yonu si oyigi, o ni eto lati gbe alamori re lo si ile-ejo lati tu igbeyawo yii ka, fun hadisi “Khansau omo Judham” o so pe: “Dajudaju baba re fi loko ti o si je adelebo ti o si korira be, o wa lo ba Anabi – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – o si fun niro pelu re, “Anabi si tu igbeyawo naa.” Sohihu Al-bukhari 6/2547 (6546).
Okunfa sise mojemu alase(waliyu) fun didara igbeyawo ni jije olusojukokoro ni gbogbo igba lori daada obirin ti npase le lori, eni to ba wa nso pe isesi yi je oun to fa gile ominira obirin nibi sisesa eni ti o yonu si lati je oko fun, ao wa so fun pe: Dajudaju islam ti fun obirin ti o ba ti balaga ti o si ni lakai yala o je omoge tabi adelabo ni eto lati so pe: mo gba abi mo ko fun eni ti o ba wa ba a ninu awon ti won fe je oko fun, ko si yonda fun alase re lati pandandan tabi foro re yala nibi ise tabi ninu okan nitori ki o le faramo eni ti ko yonu si lati je oko fun, fun oro re ojise Olohun–ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ti o so bai pe: “Won ko gbodo fi adelebo loko titi won yio fi gbase lowo re, won ko gbodo fi omoge loko titi won yio fi gba iyonda lowo re, won wa ni: Iwo ojise Olohun bawo ni iyonda re ? O wa so pe: Ohun ni ki o dake.” Sohihu Albukhori 5/1974 (4843).
Dajudaju nigbati shariah pepe si igbeyawo ti o si seni-lojukokoro si i, kii se erongba re ni lati fun ni nigbadun asiko die towo tabi lati mu erongba igba-die wa si imuse nikan, bi kii se pe erongba re ni lati se amuse ajosepo gbere ti ko ni duro, nigbati o ti owa je pe obirin ni abala keji fun ajosepo naa, sharia wa se fifaramo ati fifowosi re loranyan, amo nitori okunfa pe obirin je alanu niti adamo ti osi jepe awon nkan ti orokirika mo nlapa lori okan re, o si je eniti ntete ma ngbarata nibi awon isesi re, o si tete ma ngba itanje lopo-igba pelu ohun ti o ba han si, sharia wa fun alase re ni iyonda lati ko fun eniti o ba wa lati fe ti kii se eniti ose deede pelu re (obirin) nitoripe okunrin ni opolopo igba je eniti o nimo nipa okunrin ju obirin lo, tori pipapo won nibi jije okan nibi eya okunrin. Amo ti okunrin ti o se deede re si ba wa, ti obirin si gba fun ti alase re wa ko jale lai nidi kankan ju lati jegaba le lori lo, won yio gbe obirin yen kuro labe ase re si odo elomiran ti o sunmo o – ti o dara ju – ti o si sunmo ju, ti ko ba wa ni awon alasunmo, adajo ni yio fi loko nigbanaa.
Dajudaju Islam ko fun obirin lati fe okunrin ti ko se deede re ti ko si nibamu si i ati si awon idile re, nitoripe obirin ati molebi re ni won yio jo ma ri ebu fife oko ti ko se deede pelu re ati iyepere ati alebu tin be latara isesi yii. Fife okunrin ti alase obirin ati awon alasunmo re ko yonu si abajade re ni jija okun-ebi eleyi ti Olohun pase asopo re. Osunwon ti o daraju fun oko ti o se deede pelu omo-birin ni eyi ti oro ojise – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – toka si bai pe: “Ti eni ti e yonu si iwa re ati esin re ba wa bayin ki e ya fi aya fun, ti e ko ba lo se be fitina yio ma sele lori ile ati ibaje to po.” Almustadrok’ lori sohihayn 2/179 (2695). Nitoripe oko ti o je elesin ti o niwa ti o ba nife iyawo re yio ma se aponle re, ti ko ba nife re ko ni foju kere re ko si ni yepere re yio si maa paiya Olohun lara re.

9). Irinajo obirin laisi alasunmo re pelu re:
Dajudaju obirin ninu islam aluulu kan ni ti won ma nso ati wura kan ti won ma nse itoju re ni, ko leto lati maa fara kan tabi fowo kan ayafi eni ti o ba leto lati fowo kan. Islam lo awon ona ti yio je iso ati isora fun (isora loore ju oogun lo) nitori iyen ni o fi ko fun obirin lati se irinajo ni oun nikan laisi alasunmo re nibe gegebi oko, tabi baba, tabi omo-iya re lokunrin, tabi alasunmo kan ti won se fife re leewo fun, fun oro re ojise– ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe:”Obirin ko gbodo se irinajo ayafi pelu alasunmo re, okunrin kankan kosi gbodo wole ti i ayafi ki alasunmo kan o wa pelu re. Okunrin kan wa so pe: Iwo ojise Olohun; mo gbero lati jade pelu iko omo-ogun bai bai obirin mi si fe lo se Hajji ? Ojise Olohun dalohun pe: “o tele lo.” Sohihu Al-bukhari 2/658 (1763).
Sorosoro kan le so pe; O nbe nibi kiko fun yi onde fun ominira obirin ati dindin eto re ku ! nitoripe eleyi ni ohun ti yio bo sinu lakai ni igba akoko, amo ti a ba mo idi-oro ti a si mo okunfa sise leewofun iruju o ba ye ti yio si han siwa pe dajudaju islam pelu ise re yi o nfe lati so iyi obirin ni ati lati daabo bo., kii se lati yepere re tabi de ominira re mole. Dajudaju irin-ajo ni opo-igba eyi ti o po ju idamu ati wahala ma nwa nibe, ti obirin pelu adamo re si je eni ti o le ni abala ti ara – pelu okunfa ailero ti o le seri si gegebi ati so siwaju ninu eela (nkan-osu), oyun, ati fif’omo l’omu, ati ti emi pelu rirorun jijuwole re latara oju-anu re ati yiyara lapa re pelu awon ohun ti ma nlapa lara oun ti o rokirika re, ti awon eleyi kii se alebu fun, papaa ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ti pe won ni (qowaarir) “igo omi-mimu” ni adape fun lile okan won ati pelepele won ati nini aanu nibi igbarata won. Lati odo “Anas omo Malik” o so pe:
“Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – mbe lori irin-ajo kan ti omo-odo re okunrin dudu kan si nbe pelu re ti won npe ni “Anjashah” ti owa nkorin. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a – wa so fun bai pe: So ara re iwo “Anjashah” ma se pelepele pelu awon “igo” Sohihu Al-bukhari.
Atipe obirin lori irin-ajo re o ni bukata si eni ti yio ma sam’oju to re kuro lowo eniti o le ma rankan aburu si ninu awon elemi buburu nibi mimarankan si dukia re tabi ara re, ti o si je pe leyi ti o bori ju ni pe ko le rorun fun lati daabo bo ara re fun lile iseda ara re. Botijepe o ni bukata bakanna si eniti yio fi lokan-bale nibi awon ohun ti o nfe ti yio biya bukata re ti yio si duro ti awon alamori re ti yio si se idekun ti o pe fun. Alasunmo obirin ninu islam won nfe sise gbogbo eleyi lowo re titi ti ko fi ni nibukata si okunrin ajoji kankan. Alasunmo obirin niti otito-oro oluranlowo kan ni ti yio ma se iranlowo fun ati ode kan ti yio maa so kuro lowo eniti o ba ngbero aburu si ti o si nrankan ibaje si ninu awon enia-buruku, ki wa ni iyepere obirin ninu eleyi ? iyi lo je fun obirin ati eye, pe ki o ri eniti yio ma gbe gege ti yio ma se alekun aponle re ti yio si ma so, ti yio ma daabo bo kuro nibi iyepere awon oluyepere-eda, ti yio si ma dide si iranlowo re ti yio si ma fi i lokan-bale nibi awon ohun ti nfe ati ohun ti o ni bukata si.


SISE NINÁ AWỌN OBIRIN LEEWO NINU ISILAAMU
Lati ọwọ
* AHMOD AL’AMIR ATI TASAKURA FIFAYAN
Ọrọ ìṣáájú
Gbogbo ope ti Olohun ni eni ti O ran Muhammad ni oniroodunnu olukilo, olupepe si oju-ona Olohun pelu iyonda re ati atupa imole, o si saponle awon saabe re o si fun won ni ola ti o tobi, ki ike ati ola Olohun ki o maa ba Anabi Muhammad ati awon araale re ati awon saabe re ike ati ola ti won yio ma tele arawon lopolopo.
Leyin na:
Paapa mo ko tira yi lati fi fesi si awon iruju awon ti esu tan je ti o si sowon nu ni isonu ti o tobi, paapa won ti fon ibere nipa lilu obirin ninu islam ka ni opolopo awon aaye ijoko, a si ri opolopo ninu awon ikanrin agbohun safefe ti nsalaye oro-esin lori alamori ti ko ni ogbon ati oye nipa re, opolopo awon oni keeta wa joko lori islam nibi alamori na nibi gbogbo ibujoko ti won nda adapa iro ati eri eke ninu awon oro ti ko ni afijo tabi ipile kankan, mo wa fe lati gbe e siwaju oluka alaponle ipó islam nibi nina iyawo ati ipo re si awon esin yoku ni iyapa ti o han. Islam ni esin kan soso ti o se nina awon obirin leewo yala nigba omode ni tabi agba. Eleyi ni alaye lekunrere lori oro yii, leyinna ki e wa se idajo lori alamori naa leyin kika ati iwoye si.

Onkowe.....
Ahmod Al’amir.

Pinpin awon ise nibamu si sheria Islam

Dajudaju gbogbo awon ise omo-enia yio je pinpin labe bogi islam pelu awon ipin ti nbo wonyi titi idajo awon ise sise larin ohun ti won se leto ati eyi ti won ko leto yio fi ihan:
1). Oranyan(Fardu): Ohun ni eyi ti o ga ju ninu awon ipele oranyan esin, ohun ni ohun ti Oba asofin nfe sise re ni fifi-rinle pelu eri dandangbon ti kosi iyemeji ati iruju nibe, gegebi ase irun-kiki, awe gbigba ati kike “Al-qur’an”, idajo re ni didunimo sise re ati mimu wa pelu sisan oluse re lesan ati jije olugbejusile ni’iya.
2). Eyi ti a fe(Mustahaabu): Ohun ni ohun ti Oba-asofin pase re ti kii se lojupanna dandangbon, ti won yio san oluse re lesan ti eni ba gbe jusile ko si ni gbese, lapejuwe; rirun pako ni o ku die ki agberun (As-solat) ro.
3). Eleyi ti o to(Mubaahu): Ohun ni gbogbo ohun ti ko si esan fun sise re ko si siya fun gbigbe sile re, gegebi rinrin, ati gigun nkan ati ohun ti o jo mejeeji ninu gbogbo ohun ti won yonda nibe ninu awon ise ti a ba saaba nibi isemi ojoojumo.
4). Eleyi ti won ko (Makroo'): Ohun ni gbogbo ohun ti Oba-asofin ko ti kii se lojupanna dandangbon, ti won yio san eni ba gbejusile lesan nibi titele ase, won ko si ni je oluse re ni’ya. Sugbon won fe jijinasi re ati ikuro nibi gbogbo ohun ti o ko sinu ati awon ohun ti nbe ni ikapa re, ati aigbodo ma yiju sibe won ko si ni sesan tabi fi iya je oluse re, sugbon o seese ki pipara re ati didunnimo o se okunfa kikoja awon aala Olohun ati bibo-sinu ohun ti Oba abiyi Oba to gbongbon se leewo ninu awon ise.
5). Eyi ti won se leewo(Haramu): Ohun ni gbogbo ohun ti Oba-asofin ko ni ojupanna dandangbon pelu eri amodaju ti ko si iruju nibe, ti oluse re yio gbese, ti won yio si san olugbesile re lesan niti titele ase, ni apejuwe; sise mimu-oti leewo.
Sisopinya larin Ohun eto ati eewo:
Dajudaju mimo ohun ti oto ati sise opinya re kuro nibi eewo ni opo Islam ati itoka si igbagbo, o si sopo mo awon ise inu-okan gegebi o ti so po mo awon ise afarase, atipe ipile nibi gbogbo nkan ni eto ati iyonda, ko si eewo ayafi ti otito-oro taara ba wa fun jije eewo re, amo siso nkan di eewo ati siso o di eto ninu iwo Olohun ti ola Re ga ju lowa, nitori jije adeda re olureni, oluso nkan-dirorun, onidekun, O le se ohun ti o ba wu leto fun eda re, O si le hana ohun ti o ba wu fun won, amo titobi re ike ni o je lati odo re fun awon erusin re ati ola, O gbe eto ati eewo kale fun awon idi kan ti o ba lakai mu ti o nseri sibi anfani omo-enia funra-won, lori iyen Olohun (Oba abiyi Oba to gbongbon) ko se nkankan leto ju ohun ti o dara lo, ko si se nkankan leewo ju ohun ti ko dara lo.
Yiyipada ise lati ibi idajo kan bo si ibi idajo miran:
1). Yiyipada ise ti o leto lati ipo fife bo si ipo sise-leewo bakanna ni idakeji:
Ise ti o leto seese ki o yipada lo si ipo eewo nigbati won ba ri awon okunfa ti yio so o di ohun ti yio yipada ni ijiro fun ki o maa je ise to dara ti okan ma nfe lo si ibi ise-egbin ti o je inira fun emi. Lojuponna alaye eleyi, idajo sharia nibi mimarin-kiri ni awon oju-popo je eyi ti o leto, sugbon o seese ki idajo sheria nibi rinrin-kiri yii yipada lati ipo ohun ti o to lo si ipo eewo nigbati adajo sheria fun ilu ba gbe ofin rinrin-kiri leewo kale leyin agogo mewa ni apakan awon oju-popo tabi ni ilu ni wiwoye-si ise aabo ti o seese ki o pepe si ibi iparun eda.
Bakanna ni ise eewo naa seese ki o yipada losi ipo eto nigbati won ba ri awon okunfa ti yio so o di oranyan fun gbigba-emi-la kuro nibi iparun, gegebi oti mimu, oti mimu je eewo labe sheria sugbon o seese ki o di ohun eto nigbati ti omo-enia ba sonu ni inu-papa to wa di pe o fe parun lati ara ogbe ti ko si ri nkankan niwaju re ju oti lo, nigbana yio mu odiwon ti yio fi gba emi ara re la kuro nibi iparun ko si gbodo mu koja re.
2). Yiyipada ise oranyan lati ipo oranyan bo ipo eewo, bakanna ni ojuponna keji:
Ise oranyan seese ki o parada si ipo eewo, o si seese ki ise eewo o parada si ipo oranyan, lori iru ona ti a gba salaye si waju, irun kiki lapejuwe oranyan ni sugbon o seese ki o di ise eewo nigbati omo-enia ba nkirun ninu ila re ni asiko ti ile-riri ti o le gan ba nsele loo ti eni ti nkirun si ni amodaju pe oun le ba lo ti ko ba tete sa jade kuro ninu ile na !! kikoja-ala ni ara enikan nibi gige ese re l’apejuwe ise eewo ni, amo ti onisegun ti nse iwosan ko ba rii ona-abayo lati la alare ju pe ki o ge ese re lo, ti ko ba se be yio se okunfa iparun fun, nigbana gige ese alare ti di oranyan fun onisegun ti nse itoju, ti ko ba se be, onisegun naa yio di elese, eni-ibi ti yio si ji’ya lori ai ge ese alare naa.
3). Yiyipada ise ti won ko sise re lati ipo kiko bo si ipo ohun ti won fe, ati yiyipada ise ti a fe bo si ipo eewo: Ise ti won ko oseese ki o yipada si ipo ohun ti won fe tabi tun bo si ipo oranyan ati dandan. Kiko iyawo sile lapejuwe je ise kan ti won korira ninu idajo sheria ti Olohun (Oba abiyi Oba to gbon-n-gbon) naa si ko o, amo ni apakan awon igba aiko iyawo sile le mu ni lo sibi awon eewo sheria ti enia ko ni le bo nibe ayafi ki o ko sile, gegebi ki o ma si itiju fun obirin (alaini-ijanu) ti (oko) si kagara lati se atunse re, ohun ti a le so nipa eleyi ni pe kiko re ni o lola ju, bee ni ise ti won ko naa le di ohun ti won fe.
O seese ki ise ti won fe yipada bo si ipo eewo, rirun pako (orin) lapejuwe je alamori kan ti won fe, o seese ki o di ohun ti won ko tabi di eewo nigbati ti eyin re le mo yo, ti o si mo pe ti o ba run pako eyin re yio yo, nibi isesi yi rirun pako yio maa lo pelu ofin sheria ninu islam eleyi ti o so pe (ma fi ara ni enia, ma si fi inira se esan inira).
Nisoki:
Nisoki ohun lori oun ti asalaye yi ni pe dajudaju islam kii se esin afoju ti ko riran ti ko mo odiwon ise awon enia ati awon ikapa won ninu isemi ati isemi ojoojumo, bi kii sepe oju-fifo ni ti otito-oro inu okan awon ota re ni o wa awon eni ti won nfe lati mo fon awon alamori ti o ruju ati awon oro-iro si inu islam ti won nfe lati pa ina esin Olohun (Oba ti ola Re ga ju), Olohun ko ni sai ma pe imole re, koda ki awon kefere ko jale.
Iwo aayo mi oluka o seese ki o ti ni ooye pe dajudaju islam kii se esin abosi bi kii se pe esin deede ni, deede si je ikan ninu awon oruko Olohun ti o rewa, sise leewo ati sise leto ninu islam won mo lori deede won ko mo lori oju-fifo, amo abosi pelu gbogbo iran re eewo ni labe sheria ninu islam.

Ibasepo iyawo labe itokasi Al-qur’an Alaponle ati Sunna tomọ kanga
Labe itokasi awon oro Al-qur’an alaponle a o ri pe dajudaju Olohun (Oba to gbon-n-gbon Oba ti ola Re ga ju) ti pase sise daada si iyawo ati sise aponle re, ati bibalo pelu daada, koda ki o ma si ife atokan wa nibe, Olohun ti ola Re ga ju so ninu tira-idajo re bai pe:
Itumo: (Ki e si maa ba won lo pelu daradara. Bi e ba korira won, o le je pe e ko ohun kan ti Olohun si ti se opolopo rere sinu re) Surotu An-nisai 19.
Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun o maa ba a – nso bai pe: “onigbagbo lokunrin ko gbodo maa korira onigbagbo lobirin, ti o ba korira iwa kan lara re yio yonu si iwa miran lara re.” Muslim.
Olohun (Oba abiyi Oba to gbon-n-gbon) nsalaye pe dajudaju o nbe fun obirin awon eto kan lori oko re, gegebi awon eto kan ti se wa fun oko re lori re, Olohun wa nso bai pe:
Itumo: (O wa fun awon obirin l’ori oko iru ohun ti o wa fun oko won l’ori won pelu daada) Surotu Al-baqaroh 228.
Asoole ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ni asiko ti ipakoda re sunmo ni nini akolekan pelu awon obirin ati sise aponle won ati aigbodo mo se abosi won ati dida awon eto nu. O so bai pe: “E maa se daada si awon obirin.” Muslim.
Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun o maa ba a – tun so bai leekan si pe: “Eni ti o pe ju ninu awon onigbagbo ododo ni igbagbo ni eni ti iwa re dara ju, eni esa inu yin ni eni ti o dara si awon obirin re.” Tirimisi ati Ibnu majah 1230.
Lati odo “Aisha” – ki Olohun o yonu si – so pe: Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai pe:”Eni ti o loore ju ninu yin ni eni ti o dara si awon araale re, emi si ni eni ti o dara ju si awon araale mi ninu nyin.” Ibnu hibban ati Tirimisi 3314.
O tun pase sise suru lori awon asise re ati nini agbamora lori awon adínkù re ati amojukuro fun awon ohun ti o ba bo fun. Bakanna ni nsalaye adamo obirin eleyi ti Olohun seda re le lori. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun o maa ba a – wa so bai pe: “Dajudaju won seda obirin lati ara egungun efonha to te kokoro, ko le na fun o tan yan-yan, ti o ba wa gba itelorun pelu re oo gbadun re pelu aina-tan re, ti o ba wa ngbiyanju lati naa gbooro oo kan, kikan re si ni kiko-sile re.” Muslim.
O tun so bai – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe: “E maa se daada si awon obirin, toripe dajudaju won seda won latara egungun efonha ti o te kokokro, dajudaju ohun ti o te ju ninu egungun efonha ni oke re, ti o ba fee na a, oo kan, ti o ba fi sile ko ni ye ni tite kokoro, e ya maa se daada si awon obirin.” Al’bukhori.

Nje ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ná ikankan ninu awon iyawo re ri bi ?
Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ni awokose awon musulumi, Olohun se titele oju-ona re ni dandan fun won, (Eni ti ola Re ga ju) wa so bai pe:
Itumo: (Dajudaju ikose rere mbe fun nyin lara ojise Olohun fun eni ti mberu Olohun ati ojo ikehin ti o si ranti Olohun ni opolopo igba) Surotu al’ahazab 21.
Oun ni apejuwe ti o ga ju ati iwa ti o dara ju Olohun gbe e dide pelu esin irorun, Olohun re ko ni eko, O si se kikoleko re ni eyi ti o dara ju, awon iwa alaponle ati awon adamo ti o dara ju lo pejo si ara re, Olohun ti ola re ga ju so bai pe:
Itumo: (Atipe dajudaju ire je eni ti o ni iwa ti o dara ju) Surotu Al-qolam 4.
O lo awon iwa re alaponle niti fifi sise se lori ile, o si se e ni eyi ti awon enia nri ti won tun fara kin i, pelu oro re – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe:”Won gbemi dide ki nle ba pe awon iwa alaponle.” Moliki ati Bukhori 45.
Iyawo re “Aisha” – ki Olohun o yonu si – na nso ohun ti o mo nipa re ni abala opolopo ibase ninu eyi ti awon saabe re mo nipa re pe: “Alqur’an ni iwa re.” Ahmod lo gba a wa (4811).
Tabi ni itumo pe: O ma ntele awon ase re, o ma njina si awon ohun ti o ko, ko si iwa eleyi kan ti Alqur’an se ni loju oyinyin sibe ayafi ki Annabi je eni ti o pe ju ninu awon enia nibi fifi se iwa hu, ko si iwa buburu kan ti Al-qur’an ko o ayafi ki Anabi je eni ti o le ju ninu awon enia nibi jijina si i.
Ko wa ninu itan re – ki ike ati ola Olohun o maa ba – pe ona obirin tabi omode kan ri !!!!
Dajudaju eniti ba ma ntele itan re ati ti ba ma nronu si awon oro re abiyi yio ri pelu ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun o maa ba a) nko nina obirin osi hana re in ihana ti otobi, iyawo re A’isha – ki Olohun o yonu si – nso nipa re pe: “Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ko fi owo re naa nkankan tabi obirin kan tabi omo-odo kan ri, ayafi ki o sa ma gbiyanju si oju-ona Olohun, won ko fi suta kan ri ki o wa gbesan lara onisuta naa, ayafi ti won ba ko lu ohun ti Olohun se ni eewo, igbana ni yio wa gbesan fun Olohun (Oba abiyi Oba to gbon-n-gbon).” Muslim lo gba a wa.
Bakanna ti o fi mo awon ota re ti won ngbiyanju lati ba ipepe re je ati lati dina mo o, won ri nkankan lati se atako ohun ti aso yii rinle.
Ki a tun woye si ohun ti eni ti o sunmo julo so nipa re, ko si iyemeji nibi pe sise idunnimo yio ma salaye adamo eniti o ndunni mo ati iwa re, omo-odo re “Anas omo Malik” – ki Olohun o yonu si – eniti o se boyi sin fun ojise Olohun fun odun mewa, nso nipa re bai pe: “Mo se boyi sin ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – fun odun mewa, ko seesi so fun mi pe: sio re ri, ko si so si ohun ti mo se ri pe: Bawo loti se eleyi ? Tabi so o si ohun ti mo ba gbe ju sile pe: Kilode ti o fi fii sile ? Ojise Olohun je eni ti o dara ju niwa ninu awon enia.” Muslim ati Tirimisi.

Idajo niná iyawo ninu islam
Dajudaju ipile sheria islam ni awon tira Olohun ti ola Re ga ju ati ilana Anabi re " ki ike Olohun ati ola re o maa ba a ati awon araale re ati awon saabe re "alaponle eyi ti egbawa re dara. Lati inu mejeeji ni a o ti ma mu eri, ni abe imole mejeeji ni a o si ti ma salaye idajo nina awon obirin ninu islam. Nje ninu oranyan ni, tabi ohun ti a fe, tabi ohun ti o to, tabi ohun ti won ko, tabi ohun ti won se leewo ninu agboye hadisi eleyi ti “Iyasu omo Abd Allah” gba wa nibi ti o ti so pe: Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai pe: “E ko gbodo maa na awon eru Olohun lobirin, ni Umar ba wa si odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – o wa so pe: Awon obirin ti ngbonmu si awon oko won” ni o ba se idekun fun won lati ba won wi, ni opolopo awon obirin ba wa rokirika ile ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun ki o maa ba a – ti won npariwo awon oko won, ni ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o ma ba a – ba so bai pe: “opolopo awon obirin ti wa rokirika ara ile Muhammad ti won pariwo awon oko won, awon won yi kii se enia to dara ju ninu yin.” Abu Daud lo gba a wa ati Ibnu majah ati Ad-darimi, o dara lodo Albani.
Ni inu sise alaye hadisi abiyi ti o gba waju yi, awon ohun ti nbo yi yio ye wa yeke:
Dajudaju hadisi abiyi yii, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a –ko so ni aaye kan ati asiko kan ninu igba, bi kii se pe sso ni asiko meta ninu igba ti won yato si ara won:-
Asiko igba alakoko: O so nibe – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe: “E ko gbodo maa na awon eru Olohun lobirin.”
Lori eleyi, gbogbo eniti o ba gbo oro yii lodo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – yio mo amodaju pe dajudaju idajo nina obirin ninu islam ohun ti won se leewo ni nitori kiko o re lati odo Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – atipe eni ba nse be elese ni, yio gbese titapa si ase ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a -.
Asiko igba eleekeji: Wiwa Umar omo Khottob – ki Olohun o yonu si – ni asiko kan ti o yato si asiko ti Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – soro nibe pe: “E ko gbodo maa na awon eru Olohun lobirin.” lati pariwo awon obirin sita pe: Awon obirin ti ngbonmu si awon oko won. Ni itumo pe; awon obirin ti nsaya gbangba, ti won si ngbonmu, ti won si ndoju awon oko won bole, bayi ni ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ba se dekun nibi biba awon obirin wi, niti lilo irori re ti o gboye nibi ohun ti nsele lowolowo ati awon bukata isemi ti nsele ati ohun ti o je pe ibalopo took-taya ko le duro deede ayafi pelu re. A mo bawo ni ibawi yi yio ti ri ? eleyi ni ohun ti a o mugbo leyin asiko die nibi iwadi ti nbo.
Asiko igba eleeketa: Leyin iyonda ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – fun awon oko lati ba awon iyawo won wi awon ti won gbonmu ti won si saya gbangba si awon oko won, opolopo awon obirin wa lo si odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ti won pariwo awon oko won lo si odo re, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – wa so pe: “opolopo awon obirin ti wa rokirika ara ile Muhammad ti won pariwo awon oko won, awon wonyi ki se enito dara ju ninu yii.”
Ni asiko igba ikehin yii idajo ikehin fun nina awon obirin ninu islam wa foju han pe; ohun ti a korira re ni tabi ohun ti a se leewo ni, nigbati oko ba koja aala Olohun nibe. Eleyi ohun ti a o pada salaye re leyin-o-reyin. Nje won gboye ninu oro hadisi naa pe dajudaju ojise nla Muhammad – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – seni loju kokoro lori nina awon obirin bi ? Tabi o se eyin lori eni ti n na iyawo re bi ? dajudaju oro re – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – eebu nbe nibe ati fifagile riri ore fun eniti ba n na iyawo re !!!
Paapa awon saabe – ki Olohun o yonu si won – ti ni agboye eyi ti o se deede oro ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – won mo amodaju pe eniti ba n na iyawo re ko le ri iyonu ati oju-rere ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a -, ko si siyemeji nibi pe ohun ti ko ba yo ojise Olohun ninu yio ko sinu ohun ti won kanpa mo kiko re leyi ti o seese ki o di ohun ti won se leewo.
Koda nigbati “Fatimo omo Qaysi” ko oko re sile, awon ti won fe lati fi saya ba soro leyin igbanan, lara won ni “Mu`awiya” ati “Abu Jahm” ati “Usamoh omo Zaid”, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – wa so fun nigbana pe: “A mo Mu`awiya okunrin ti o tosi ni ko ni owo lowo, a mo Abu Jahm o ma n na obirin gan, sugbon Usamo omo Zaid..” Ni obirin naa ba so bai leni ti nfowo juwe pe: Usamo! Usamo.”Sohihu Muslim.

Nje o rorun ki niná obirin o yi pada lati ipo ohun ti won kọ bọ si ipo ohun ti won se leewo ?
Paapa a ti ri ipile ati idajo alakoko ninu islam nibamu si nina obirin pe ohun ti won se ni eewo ni leyinna ni o yi pada si ipo ohun ti o to fun awon okunfa ati awon ipepe kan ti a sadayanri, leyinna ni o yipada si ipo ohun ti won kanpa mo kiko re gan, sugbon igba wo ni nina obirin yio je eewo ? Nina obirin yio je eewo nigbati o ba je ikoja aala ti ko nidi. Gbogbo aworan ikoja aala ninu islam eewo nigbati o ba je pelu abosi ati ikoja aala. Olohun ti ola Re ga ju so ninu Tira Idajo Re ni Eni ti nwa wa ni’sora kuro nibi gbogbo iran abosi pe:
Itumo: (Enikeni ti o ba se abosi ninu yin A o fun u ni iya ti o tobi to wo) Surotu Al’furqon 19.
Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun o maa ba a nso bai pe: “e paiya abosi ni sise, dajudaju abosi sise ninu awon okunkun ojo igbende ni.” Muslim.
Lati odo Anas – ki Olohun o yonu si – o so pe: Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai pe: “E beru epe eniti won bosi, koda ko je keferi ko ni si gaga kankan ti o le di (epe re) lona.” Ahmod, o dara l’odo Albani.
Islam ko fifi suta kan enia eyikeyi tori o je pelu gbogbo aworan ati eya re koda ki o je oro-siso, fun oro Oba ti ola Re ga ju pe:
Itumo: (Dajudaju awon eni ti won da adapa iro mo awon adelebo ti nwon ko ara won duro kuro nibi isekuse ti nwon je olugbagbo ododo, A ti sebi lewon laiye ati l’orun, atipe iya ti o tobi mbe fun won.) Surotu An-nuur:23.
Tabi ki suta o je pelu ohun ti won nri pelu nina ati ohun ti o jo o ninu aworan suta ayafi pelu eto, fun oro Olohun ti ola Re ga ju to so bai pe:
Itumo: (Atipe awon eni ti nni awon onigbagbo ododo l’okunrin ati awon onigbagbo ododo l’obirin lara laije nipa ohun ti nwon se, dajudaju nwon ru eru iro ati ese ti o han.) Surotul’Ahzab 58.
Tabi ki suta o je jije ohun-ini pelu ibaje, Olohun ti ola Re ga ju nso bai pe:
Itumo: (E ko gbodo je ohun-ini yin larin ara yin pelu eru) Surotu Al’baqaroh 188.
Gbogbo awon abara ni won ri bakanná nibi eleyi ako ni ati abo, omo kekere ni abi agbalagba, musulumi ni abi keferi. Lati ọdọ Abu huraira lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a – pe: “Musulumi ni eni ti awon enia la nibi ahon ati ọwo re, olugbagbo ododo ni eni ti awon enia fi okan tan a nibi eje won ati dúkìá won.” Sun anu An-naami, o dara lodo Albania.
Eni ti o ba so pe dajudaju isilaamu nse ní lojú oyìnyín lori kì koja aala tabi sisọta tabi nina obirin o ti parọ mọ ẹsin Ọlọhun ni irọ ti o tobi.

Ofin idajo sharia Islam nibi niná obirin:
Idajo isilaamu nmu alamọri niná obirin ati fifi suta kan lati ọdọ ọkọ re ni mimu ti o le ati aifi owọ dẹngbere mu u pelu biba oko wi lori kiko ja aala pelu iyawo re, o si nlo ibawi yii ni lilo imo nibamu si ofin sharia nibi ìṣesí gbigbe irufẹ awon alamori be lo si ile idajo, ni apeere:
1). Iwe’royin Riyadh fonka si ori adirẹsi re ti onina lori ero aiye lujara(Internet) ni ojo 12/12/2012 iro to nbo yi:
Ile-ejo to nri si eto omo-enia ni abe akoso “Qotif “ni ilu Saudi Arabia se idajo lori oko-iyawo kan ti o koja aala lori iyawo re pelu fifiya je, pe ki won o na ni ogbon bilala ni gbangba walia ki o le je arikogbon fun elomiran ninu awon olurekoja aala lori awon iyawo won. Bakanna lo tun se idajo pe ki o lo ko eko fun ojo mewa ni okan ninu awon ile eko akanse to nri si abala bi a ti ngbe pelu iyawo ati ìṣesí awon ebi, ki o si tun se idanwo alafowo se ti won yio ko mo iwe ejo naa.
Lori aworan kan-na nibi alamori yi dajudaju gbogbo awon ile-ejo ni gbogbo ilu isilaamu ni i ma nje oko ti ba nkoja aala lori iyawo re ni iya. Ninu eyi ti o sowan ju nipe apakan awon obirin ma nse ideruba, ti won ma nkilẹ, ti won ma ndete si awon oko won, ti won yio fa apá si ara won ni apá ti o mo niwon, leyin na won yio gbe e lo si ago awon olopa lati sise to pipe oko won lejo niti abosi, lati yepere oko re ti ko m’ọwọ-m’ẹsẹ.
Eri oro nibi alamori naa nipe dajudaju musulumi, onilakai, eni ti ntele awon eko isilaamu ko ni yonu si sisabosi obirin ati kikoja aala lori re, gegebi o ti je pe esin wa ko ko wa tabi pa wa lase pelu eleyi, bi kii se pe o se ni eewo fun wa ti o si se ninu ohun ti abosi ati eewo ko sinu, o si pa wa lase sisamojuro, ati ki ija tan ninu-eni, ati suuru, ati isedekun fun-ni, ati fifi daada ti aburu lo. Ni amodaju nipe isilaamu ko se nina obirin ni alamori kan ti o leto, bi kii se pe o se ni ayafi ni awon aaye kan ti isemi loko-laya ko le rorun nibe ayafi pelu re, o si fi awon majemu kan de e ti yio so lilo sibe di ohun ti o sowon gan lati mu erongba kan soso wa si imuse; ohun ni sise isọ lori ile ati iwa rere ni awujo lapaapo.

Awon idajo sheria nibi ìṣesí orikunkun iyawo
Ti olusọro kan ba so pe: se ko wa dara ju fun okunrin lati se isiti fun iyawo re olorikunkun ju nina re lo ni, a o so fun pe bee ni, atipe eleyi ni idajo Olohun, Ẹni ti o ṣọ ninu Tira onidajọ rẹ bai pe:
Itumo: (Ati awon ti e nberu sise orikunkun won, e ṣe kilokilo fun won, e ta kete si ibusun won, ki e si lu won; sugbon ti won ba teriba fun nyin, e ko gbodo wa ọna (ija) pelu won, dajudaju Olohun je Oba-giga Olutobi) Surotu An-nisai 34.
Ojise Re alaponle – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai ni asiko Hajji idagbere pe: “E teti gbo o, ki e ya ma se daada si awon obirin, oluranlowo ni won je fun yin, e ko nikapa nkankan lodo won ju iyen lo, ayafi ti won ba hu iwa-ibaje ti o foju han, ti won ba se be, e deye si won lori ibusun, ki e si na won ni nina ti ko ni apa nnu, sugbon ti won ba teriba fun yin, e ko gbodo wa ona (ija) pelu won. Ẹ teti gbọ o, eni eto lori awon obirin yin, awon obirin yin na si ni eto lori yin.” At-tirimisi, o dara lodo Albani.
Bai ni a se ri bi Olohun se salaye nibi idajo re ti o loore ju pelu lori ìṣesí awon erusin re, ati bi ojise Re alaponle se salaye ona iwosan isoro iyawo olorikunkun, o wa se iwosan yii pelu awon ipele meta:
1). Ipele alakoko:
Ki oko iyawo gba ona wasi ati isiti gegebi ona lati ṣàtúnṣe iyawo olorikunkun, ki o to lo si ona ideyesi lori ibusun, títò yi je oranyan lodọ agbarijopo awon Alfa onimo-ẹsin, o wa di oranyan fun okunrin lati fa ọkan iyawo re mora pelu oro pelepele ati mima fun gbọ ninu awon irọ ti yio ma mu ọkan lẹ, yio si maa mu mọ bi o ti je pataki to lọdó re, atipe o je eni ti o nifẹ daada. ki o si maa lo gbogbo ìkápá re sibi isiti fun ati sise waasi fun leni ti ngbiyanju lati se atunse ìṣesí re, ni amodaju pe waasi ti oba wa lati inu ọkan gbigbẹ ati pẹlu awon ile koko ko le sa nfaani, bi kii se pe pelu pẹlẹpẹle nibi orọ-sisọ ati ibagbe pelu pelepele gegebi rira ẹbun fun iyawo titi yio fi maa gbo oro si oko re lenu pelu iyọnu ọkan ati emin ti o dara. Pẹlu iwa yiI, o di ọranyan lori iyawo ti o ni lakai ti o si je oniwa rere ki o gba waasi lati enu oro ọko re, ko gbajumo ohun ti nbe ni iwaju re, nibi gbigbajumo awon ọmo re. A mo ti obirin ba je alagidi oniwa buburu ti isiti ko ni se ni anfani ati waasi ati itosona, ti oko ba lo gbogbo ìkápá re lori eleyi tan yio wa bo si ipele eleekeji nibi títò-tẹle gegebi Olọhun (Oba abiyi Oba to gbob-n-gbon) ti pa wa l’asẹ, ohun ni didẹye-si lori ibusun.
2). Ipele eleekeji:
Ki oko o gba ona ideye-si lori ibusun; ohun ni ki o koyin si lori ibusun ki o ma ba sere ni ibasere ọko-iyawo fun ọjo meta gegebi aala ti o pọ ju, fun orọ ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun o maa ba a-ti o so pe “Ko leto fun musulumi kan ki o deyẹ si omo-iya re kọja ojọ meta.” Muata, won fenu ko le lori.
Titi yio fi je ki o furamọ pe oun ko yonu si ìṣesí re. Ona abayo yi ni ibamu si anfani keji fun iyawo lati ye ara re wo larin asiko yii ti se ojo-meta – anfani lati ronu, toripe ti o ba deye-si ju igba yii lo, pelu eleyi yio fiya je, ti o ba wa ye ara re wo to si seri pada sibi sise daada, o di oranyan fun u (oko) lati fagile dideye si i, ki o si samojukuo fun u, ko si ha asise re danu fun u, ti o ba n ba bẹẹ lọ, to nsagidi, to nsegberaga, to ngapa ti ko wa ri anfani dideye-si re si i, yio bo si ipele elẹẹkẹta.
3). Ipele ẹlẹẹkẹta:
Ti okunrin ba gbiyanju lati ṣàtúnṣe iyawo re olorikunkun pelu isiti,waasi, oro to dara ati awon ebun, sugbon ti ko se e l’anfani, leyin na o tun gbiyanju ona ideye-si lori ibusun ati sise afihan aidunu-si re si ìṣesí re, sugbon eleyi na ko tun se e ni anfani, nigbana ni won se niyonda fun okunrin lati ba iyawo re wi pelu nina a ni nina ti ko ni apá nnu ti ko si ni oripa. Paapa agbarijopo awon Alufa ti fenu ko lori oranyan ìtòléra-won yii gegebi ona abayo si isoro iyawo olorikunkun, ohun ni waasi leyin na ideyesi lori ibusun leyin na ni niná. Paapa “Atoou” ti so pe: Mo bi “Ibnu Abbas” leere pe kini niná ti ko ni apá nnu ? O so pe: Pelu orin (pakó) ati ohun ti o jọ!!. “Alhasan Albasiri” wa so pe: itumo re ni niná ti ko ni oripa”.
Nitori t’Olohun iwo ọre mi pataki to nka iwe yii, iru ọgbe wo ni pako le fa (ohun ni igi tẹẹrẹ kan ti gungun re ati kiki re ko ju deede gege-ikọwe lọ) ? Njẹ o rọrun ki won pe niná pelu rẹ ni niná ti o lagbara ti o si le koko. ?
Ti o ba ri si pe ti oko ba ná iyawo re ni niná to mọ niwọn pelu orin ni nina to lagbara, wa tele mi bakanna lati woye si melo-melo ninu awon ere-oritage awon gẹẹṣi ti won ngbe jade ni “Holand” ati ibomiran ti o yato si i, ti nya aworan fun wa ọrọ imunubini larin okunrin kan ati omiran, tabi larin okunrin kan ati obirin kan, tabi larin oga ìlèṣe ati awon osise abe akoso re, larin ere yii, ikan yio gbe ika-ilabe re si ori-igbaya elomiran leni ti nwa nisora tabi titi yio fi f’ika ifabẹla re ti danu tabi pelu gege-ikowe ti nbe lowo re ti yio fi kan a nigbaya, ni opolopo ninu awon asiko, ẹni yi le gba elomiran leti. Nibi opolopo ninu awon ere-oritage won; iyawo nibi oro siso pelu oko re le di eni ti yio gba oko re l’eti ni gbigba leti ti o lagbara abi larin iforo toro larin awon mejeeji ki oko re gba leti leyinna yio si peyin da. Gbogbo eleyi ni awon geẹsi ko ka a si ohun ti oun ibaje larin oko-laya, bi kii se pe o jẹ igbarata ti o mu oko tabi iyawo gba ikeji re leti. Won a si tun maa kaa si pe dajudaju okọ yii tabi iyawo yii je enikan ti o ni ọlaju, ni amọndaju pe gbigbani leti ninu isilaamu je eewo, won kan ntako Islam ni, won si nparọ mọ ọ pe o n seni lojukokoro lori ilekoko.
Pelu pe dajudaju isilaamu ti yonda fun okunrin eleyi ti o ti lo ìkápá re ni ipele alakoko ati eleekeji ki o bo si ipele eleeketa, bee naa ni Islam ti fun obirin ni eto kan siwaju bibo si ipele yii tii se bibere fun kiko-silẹ ti a mọ si itusile (khuliu`)
Ni amodaju pe awon ipele won yii; isiti, leyin na ni ideyesi leyin nipari ni niná kii sii se ona-abayo fun awon isoro ojoojumo larin oko ati iyawo, bi kii se pe ona atunse si awon isoro nla larin awon mejeeji. Ni apejuwe ti oko ba ṣọ fun iyawo re pe: se ireṣi ati ẹja fun wa loni, ni iyawo ba gbagbe lo ba se iresi ati adiẹ, nje won yio lo idajo yii sibi eto re yii, pe ki o se isiti fun u tabi ki o dẹyesi tabi ki o ná a ?!!!.
Ni otito ko ribẹ, eleyi ni awon alamọri ibasaaba ti o sọranyan ki o lọ pelu alafia ti ko gbodo si eebu nibe, a mo ti iyawo ba je obirin oniwa buruku olorikunkun ti oko si ti bẹre si ni ri i pe o ti fe ma se asise ati iwa aida ati iwa ẹṣẹ ati igberaga ati motomoto !! nibi yii o, ohun ti a le sọ nipa obirin olorikunkun yi ni pe o ni bukata si ki won o se atunse re ati itosọna ati iwosan si isoro re gegebi alaisan eleyi ti o ni bukata si óógún. Wa fi ori ya aworan re pelu mi iwo oluka, enia mi tootọ; mimo bẹ obirin na lori agidi re ati igberaga re ati mimo bẹ re lori awon ìṣesí eleyi ti o je pe lati ara re o le ba ile re je ti o si le ti be fa kikọ-silẹ. Paapa oko ti lo pelu re fun asiko ti o pọ pelu ipele isiti ati itosọna ati ideyesi lori ibusun, sugbon ko ti ẹ daun si gbogbo eleyi, ewo ni o wa lọla ju ninu mejeeji bai; se kiko-sile ni tabi niná ti ko ni ọgbé nnu ?!! Ti niná ba jẹ oun ti oju re da, ti ikọsilẹ si je eyi ti oju re fọ, dajudaju eyi ti o da lọla ju eyi ti oju re fọ lọ.

Itumo ati ohun ti gbolohun niná nda le l’ori ninu Islam
Siwaju ki awon eleto ati ajijagbarata fun awon ẹto omo-enia lagbaye to da si lile koko mọ iyawo ati awon ọmo, paapa Islam ti gbawaju nibi eleyi pelu si se e leewọ, o si ka eniti ba n si ẹlẹṣẹ ti o lẹtọ si íyá aiye ati ọrun. Eleyi je ofin to pe ju ofin ti ifiya je ni ko koja ile aye nikan, lati bi ohun ti o ju ẹgbẹrun ọdun kan ati irinwo lọ (1400) ni ojiṣẹ nla Muhammadu – ki ikẹ ati ola Olohun o maa ba a – ti ṣọ pe: “Musulumi ni ẹni ti awon enia la nibi ahọn ati ọwo re, olugbagbo ododo ni eni ti awon enia fọkan tan lori ejẹ won ati dukia won.” Ahmod ati Tirimisi ati An-nasahi, o dara o si ni alafia lọdo Albani.
Paapa o tun ti so bai lẹẹkan si – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe: “Kii se olugba lododo ni eni ti ba ma nsepe, ti ba ma nsẹbi le enia, ti ba ma nhuwa ibajẹ, tabi ti mo nsọrọ ibajẹ lẹnu.” Bukhori lo gba a wa, ati Tirimisi, o lalafia lọdo Albani.
O tọ fun onibere ki o bere pe kilode ti Islam fi sọrọ lori fifagile ilekoko ti o si tun se niná obirin olorikunkun lẹtọ ni asiko kanna ?!
Fun ìdáhùn si ibere naa, o sọranyan ki akọkọ salaye iyatọ larin ohun ti niná nda le lori ninu isẹmi wa ojoojumọ laiye isin yi ati itumo rẹ ninu Sharia. Ninu isẹmi wa ti asiko yiI, nigbati ẹnikan ba gbo pe okunrin kan na iyawo rẹ, nigbana ni aworan buruku ati ibanujẹ yio wa si inu irori re si ọko iyawo alagidi alabosi yii, ni eyi ti o le fa ki o maa yẹpẹrẹ iyawo re pelu gbigbaloju gbanipa, ati aworan kan si iyawo naa ẹni ti won se abosi re, eni ti kikọja-ala selẹ le lori ti ara re kun fun awon apá, ọgbé, ati orisirisi arunki. Eleyi ni itumo nina ni irori ti aba saa ba. A mo ti nba ṣọ fun ọ pe mo lu agogo ẹnu ilẹkun, se oo gbọye nigba yẹn pe mo kọja aala lara ilẹkun pelu lilu ?!! Tabi ti nba so fun ọ pe ma fi apejuwe lelẹ fun ọ, nje oo gbọye pe ma kọja aala lara apejuwe pelu fifi lelẹ ?!! Ajepe nigbana gbolohun niná ma nyi pada yanyan nibamu si lilo ninu ede ati nibamu si erongba eni ti nsorọ ati ipo re ati iwa re. Gbogbo eleyi ni yio ya aworan itumọ gbolohun niná sinu laika wa. Nitori eleyi dajudaju agboye gbolohun niná ninu Islam yatọ gedengbe si agbọye re nibi lilo wa ojojumo. Agboye niná nnibamu si agboye wa ojojumo eewọ ni, ise ẹṣẹ totobi si ni ninu Islam. Lori eleyi kosi ọna fun pipade agbọye mejeeji lailai, ikookan ninu won ntako ekeji ni. Ti a ba fe se deede osoranyan ki a ṣọ pe ko si niná iyawo ninu Islam won ko si yọnda re, bi kii se pe Islam kọ yiyeperẹ re ati sisaburu si tabi fifi ahọn buruku ba ṣọrọ. A mọ agbọye gbolohun niná ninu Islam ntumọ si niná kan gẹgẹ bi egígé to mọ niwọn bi a ti se apejuwe (bi lilu ago) leyi ti won kan gbero lati jẹ ki iyawo o mọ pe alasise ni oun nibi ẹto okọ re, atipe ẹto nbẹ fun oko re lati se atunse re ati lati mu duro deede. Paapa Islam ti gbe awon ipele ka lẹ fun oko lati fi koju isoro iyawo olorikunkun, ohun ni awon ipele ti o gbawaju ipele niná, o wa se niná ni ipele ti o kẹhin fun awon eni ti awon ọna abayọ miran ko ba sanfani fun. Paapa Islam ti gbe orisirisi awon ọna iwasọra kalẹ fun okọ, eleyi ti o jẹ pe ti o ba re kọja re yio di elẹsẹ olurekọja aala Olọhun ti yio lẹtọ si iya aiye ati t’ọrun, awon ipele na niyi:
Awon onde fun kikọni-lẹkọ pẹlu niná:
1). Lilo osirisi ona nibi wiwa ojutu si iṣoro: Ohun ni ki o lo ìkápá ati igbiyanju re sibi ipele meji to gbawaju niná nibi sise waasi ati isiti ati itọsọna leyin na ni didẹyẹsi lori ibusun.
2). Ki niná o jẹ pelu orin (pako) tabi ohun ti o jọ ọ, tii se igi tẹẹrẹ ti ko le kọja deede gege-ikọwe ni gungun ati kiki.
3). Kiko gbigba loju tabi gba ni awon aaye eewu ninu ara re: Dajudaju Islam se niná oju leewọ koda ki o jẹ pe ẹni ti won nna jẹ okunrin tabi obirin, ti o tun fi mọ awon ẹranko, oju je aaye ọwọ ti kikọlu re si ma nko suta ba awon aaye imọnkan ninu ara, bi won ti se e leewo bakanna; kikọlu awon aaye ewu ninu ara, ti o si fi ọwo lile mu eleyi. Awon iyen ni aala Olohun ti eni ba rekọja re ti di ẹlẹsẹ.
4). Ki kiko-lẹkọ kogbo je loju awon enia nibi eyikeyi ìṣesí ninu awon ìṣesí. Ko lẹtọ fun okunrin lati maa ná iyawo re niwaju awon enia, awon omo re, nitoripe iyepẹre nbe ninu eleyi fun obirin lakọkọ leyin na yio tun se okunfa ríre bu fun awon omọ lẹẹkeji, rire wo ni oko yi fi nre awon omo re to je pe o nná iya won niseju won tabi ni eti igbọ won ?.
5). Ki niná na o ma je eyi ti oni ọgbẹ nnu, ti oripa re yio han lara iyawo naa gegẹbi ki o gba ẹjẹ lara re, tabi ki o sokunfa ki o da ọgbẹ ati arunki si lara. Oko ti o ba da ọgbe tabi arunki si iyawo re lara ẹlẹṣẹ ni. Iru oko bẹ je eranko ọdaran ti ko fẹ daada fun iyawo re ju pe o fe ma gbẹsan lara re lọ ati lati sokunfa didaarẹ si lara lasan. Nibamu si sharia Islam osoyan ko foju ba ile-ejo lati fiya jẹ ẹ labẹ ofin.

Niná awon obirin ninu awon ẹsin miran
Dajudaju alamori nipa niná iyawo kii se alamori asiko kan tabi aaye kan ti o so pọ mọ igba kan tabi awujo kan ni pato bi kii se pe o nbe ni gbogbo awujọ ati nigbogbo igba asiko laisi ayafi. Eni ti o ba wa fẹ lati mọ nipa ipó obirin ni awon awujọ ti o ti re kọja, o mbe ọpolọpo iwe ti o sọrọ nipa abala yi ati nipa ipó obirin ni awujọ awon Yahudi “Jew” ati awon Roomu ati awon Saina ati awon India ijọun...titi de ìparí. Lori eleyi, bawo ni ẹsín Yehudi ati Nasara ti se pẹlu niná obirin ati eleyi ti o jẹ alamọri ti won ti ba saaba ti o si tan ka gbogbo awujọ ti o ti pẹ ti o fi mọ asiko asiwaju Mesia gan. Nje asiwaju Mesia – ki ọla Olohun o maa ba a - ṣọrọ nipa niná obirin rara bi?!!! A bi se won ri ninu iwe mimọ awon Nasara yala majemu lailai tabi tuntun awon ọrọ ti nṣọ nipa sise niná obirin ni ohun eewọ tabi ohun ti won kọ ?!! Ni ibi sise iwadi yio fojuhan pe kosi nkan ti ntoka si eleyi.
Ti Nasara(Kiristeni) kan ba ná iyawo re njẹ yio gbẹṣẹ bi ti won yio si fesu kan gegebi ẹlẹsẹ ni abala ẹsin. Ki wa ni ijiya re ni ibamu si awon ọrọ iwe mimọ ? Laisi fanfa kosi ese fun, nitori ai ri ọrọ kankan ti ntọka si eleyi ninu iwe mimo, majẹmu lailai ni tabi majẹmu tuntun!!
Bakanna won ko ni fi ẹṣẹ re bi ni abala ofin, won ko si ni fiya jẹ ayafi ti oripa ikọja aala lori iyawo ba fi ojuhan gẹgẹbi ki didalapa, tabi oju-apá, tabi ki o fi nkan ya l’ara. A mọ ti amin kankan ko ba foju han lara obirin naa, bawo ni yio ti wa fi niná re rinlẹ!!! Pẹlu itumọ miran, niná ti ko ba ni apá ko si ijile le lori labala esin ati ofin lọdọ won!!!
Bakanna ki a tun woye si ẹsin Yehudi, ati Buudhiyah(Buddhism), njẹ awon ọrọ ti nse niná obirin leewo mbe nibe ?!!!
Ni nti kosi iyemeji nbe nipe ko si eyikeyi orọ esin kankan ninu eyikeyii ninu ẹsin ti o se niná awon iyawo leewọ ayafi ninu Islam nikan!! Ti o fi mọ piparada niná iyawo lati ipó eewo bọ si ipó kikọ, dajudaju Islam ni ẹsin kan ṣoṣo ti o ṣọrọ lori sise niná obirin ni ohun eewo!! A mọ awọn ẹsin ti o ku, won ko mẹnu ba idajọ yi ni sanpọnna boya pẹlu sise e leewọ ni o tabi sise e ni ohun ti won kọ.
Bi o tun se jẹ pe eyikeyii ninu awon esin o mẹnu ba awon ounde tabi awon aala ti nbe fun niná obirin ayafi Islam, nitumọ pe ti oko-iyawo kan ti o jẹ nasara ba padanu ìkápá lori ẹmi ara re ni asiko kan ti o fi wa ná iyawo re, ki ni awon ounde tabi awon aala ti oje dandan ti kogbodo re kọja re ? Njẹ ẹsin Nasara sọ nipa awon aala ti mbẹ fun okọ nibi niná iyawo re, gegẹbi pe ko gbọdo ná oju rẹ tabi ki ogba ogbe lowo re.. ? Ni nti kosi iyemeji nbe ni pe ko si.
Oluronu si ohun ti nsẹlẹ lojoojumọ eleyi ti a nsẹmi nibẹ yio ri pe awon onka kan oni osuwon fun niná iyawo lati odọ awọn ọkọ wọn ninu awon Nasara tabi Yehudi tabi awon miran yatọ si won yatọ si awọn musulumi. Iwọ naa funra-rẹ lọ wo iwe akọsilẹ awon olopa ati awon isẹle ni awon ile-ẹjọ Amẹrika ati yurobu, oo ri awon onka ti ko se ka fun ọpọlọpọ awon okọ-iyawo ti won mo nlo lile pelu ẹbi,iyawo ati awon omọ wọn!!!
Koda awujo igba aimọkan siwaju Islam, awon larubawa ma nná awon iyawo won ni bilala gẹgẹbi won ti se n na ẹru, ti o si jẹ alamọri kan ti won ti ba saaba ti kii se ẹṣẹ, ti ki si se eewọ ninu ofin kankan. Sugbon nigbati won gbe Anabi muhammadu – ki ikẹ ati ọla Ọlohun o maa ba a – dide, o fagile alamọri naa ni fifagile ti o lagbara gan, o wa sọ bai pe: “Ẹni kọọkan ninu yin yio ma ná iyawo rẹ niti nina eru, ti o si see se ki o tun sun mọ ni opin ọjọ rẹ yẹn.” Bukhari ati Muslim.
Ninu hadisi yii, Anabi – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – yọ alebu okunrin ti nná iyawo re lọsan gan fun, lẹyinna ti otun wa wa lalẹ ni ẹni ti ngbero lati sun mọ ọ!!

Awọn oro nipa ipó obirin lati inu iwe mimọ majẹmu lailai ati majẹmu tun tun:
Ni opolopọ igba ni awon leyin kristi ma nso fun wa pe dajudaju asaaju Al’mosihu(Jeesu) – ki ola Olohun o maa ba a – ni oludaabo-bo akoọkọ fun awon ẹtọ obirin, atipe oun ni eni ti o fun u ni awon eto ti eyikeyi ẹsin miran ko fun u, atipe dajudaju iwe mimọ gbe si ipo to se deede, o si se agbega ipo re !!! sugbọn se orọ yii ri bi won ti nso ?!!!
Gbogbo enia lo mọ pe dajudaju iwe mimọ se leewọ fun obirin lati wọ inu pẹpẹ inu sọọsi, ohun ni eyiti won fi ma nya awon ẹni mimọ si mimọ tabi aaye itọju awon iwe mimọ, yala obirin na jẹ ọmode ni, tabi ọdọ, tabi ọmọge, tabi agbalagba ṣiṣi, alamọri na ko nise pelu ọjọ-ori bi kii se pe pẹlu ẹya obirin. Iwe mimọ ko si mu wa si iranti yala ninu majẹmu lailai tabi tuntun eyikeyi itọkasi fun sise wiwọle obirin si inu amure (pẹpẹ), bakanna si won ko se ni iyọnda fun obirin lati ri asiri agbara awon awon alufa ijo lailai. Obirin kii se ẹni ti won yọnda fun lati maa sọrọ ninu sọọsi, kii si se ẹni ti won yọnda fun lati maa kọse eyikeyi bi won se ndi agba alufa ijo, ohun ti won se leto fun u ko ju lati kọṣe Shamosa tin se ipo boi sin!!! Paapa iwe mimọ ti kaa fun wa; awon iran agba alufa ijo ti gbogbo won si je lati inu okunrin, yala awon baba agba alufa ijo gẹgẹbi Nuhu, Ayyub, Ibrahim, Isiaq ati Ya’qub, tabi awon agba alufa ijo Aaroni tabi awon agba alufa ojise ijo ati awon arole won ati awon agaba alufa ijo oba Saadiku, gbogbo re pata pẹpẹ awon okunrin ni, ti o ba jẹ pe o lẹtọ fun obirin lati kose eyikeyi ninu ipo awon asiri pẹpẹ won yi, ko ba jẹ asaaju lobinrin Mariyama ẹni ti ọkunrin ko fọwọ ba ri, ni ko ba jẹ ẹni akọkọ lati kọse awon ipo asiri pẹpẹ won yi, sugbọn ni ibamu si awon ẹkọ ẹsin Nasara obirin jẹ ẹni ti won kọ fun nibi eleyi !!!
E je ki a mu oro die wa ọrọ wa lati inu iwe mimọ ki a le ri ipó obirin ati aaye rẹ:
1) Wọn yio jẹ obirin n’ya pẹlu ẹsẹ ọkunrin:
Iwe Jeremaya (34: 23): “Bi wooli kan tabi alufaa kan tabi enikeni ninu awon enia wonyi ba wi pe oun nje isẹ Oluwa, n oo jẹ oluwa re ati ile re niya.”
2). Didana sun obirin oni ṣina (pansaga):
Iwe Lẹfitiku (9: 21) “Ti Omọ alufaa lobirin kan ba ko ere bara re pelu sise agbere, dajudaju oti ko baba re naa mere, sisun ni ki won dana sun ọmọ náa.”
3). Gige ọwọ obirin fun awon idi ti ko ba lakai mu:
Iwe Deuteronomy (11: 25): “Bi okunrin meji ba nja, ti iyawo ọkan ninu won ba sáré wa lati gbeja oko re ti won nlu, ni oba na owo re ni o ba fa nkan ọkunrin ẹni ti ń lu okọ re yii, gige ni ki o ge ọwo re, o ko gbodo saanu rẹ rara.”
4). Obirin ti won kọ silẹ ati opó ati onisina (agbere) bakanna niwon:
Iwe Lẹfitiku (9: 21): “Enikeni ti o ba jẹ alufaa agba....Obirin ti ko ba tii mọ okunrin ri ni o gbọdo fẹ ni iyawo. Ko gbodo fi opo se aya tabi obirin ti oko re ko sile, tabi obirin ti o ti mọ okunrin, tabi asewo; ko gbodo fe eyikeyii ninu won. Obirin ti ko tii mo kunrin ri ni ki o fe laarin awon enia re. Ki o ma baa so awon ọmọ re di elese laarin awon enia re; nitori pe emi ni Oluwa, to mo sọ ọ di mimọ.”
5). Titẹriba obirin ti won kọ silẹ fun ọkọ rẹ:
Iwe ti Bolisi kọ si awon ara efesu (22: 5): “Mo pe ẹyin obirin ki ẹ ya ma tẹriba fun awon ọko yin gegebi ti Oluwa, toripe okunrin ni olori obirin, gẹgebi Mesia bakanna ti jẹ olori ijo, o jẹ olugbala ara, sugbon bi ijọ ti ntẹriba fun Mesia, bẹẹ gẹlẹ ni ki awon obirin maa se fun awon ọkọ won nibi ohun gbogbo.”
6). Jijẹ dandan fun obirin lati dakẹ ninu sọọsi:
Iwe alakoko ti Bolisi ko si awon ara Korinti (34: 14): “Ki awon obirin yin ya mo panumọ ninu soosi, a ko gba won laye lati sọrọ, won ni lati wa ni ipo iteriba, gẹgẹbi ofin ti wi, bi nkankan ba wa ti won fe mọ, ki won bi awon ọkọ won ni ile. Itiju ni fun obirin lati sọrọ ninu soosi.”
7). Obirin ni okunfa iparun (anú):
Iwe alakoko ti Bolisi ko si Timoti (11: 2): “Obirin ni lati maa fi ifarabale kẹkọ pelu iteriba. N ko gba fun obirin lati jẹ olukọni tabi lati ni asẹ lori okunrin, ki obirin maa panumọ ni. Nitori Adamu ni akoko da, ti Efa si tele. Ki i se Adamu ni ogba itanje, obirin ni ogba itanjẹ ti o fi di ẹlẹsẹ. Sugbon a óo gba obirin la nipa ọmọ-bibi, bi awon obirin ba duro lai yẹsẹ ninu igbagbọ ati ife ati iwa mimọ pelu ikora-ẹni nijanu.”
8). Ijopomulero ọkunrin lori obirin:
Iwe alakoko ti Peteru kọ (1: 3): “Bakan náa ni ki ẹyin obirin máa bọwo fun awon oko nyin...Ewa yin ko gbodo je ti oun afi han bii irun-didi, ati nkan ọṣọ wura ti e ko sara ati asọ-igba. Sugbon ki ẹwa yin je ti ọkan ti ko han sode, ọkan irele ati iwa pẹlẹ. Eyi ni ẹwa ti ko le sa, eyi ti o se iyebiye loju Olohun. Bayi ni awon obirin mimo ti ri ni ati johun, bakanaa awon olugbara le olohun lobirin, won yio mo bọwọ fun oko won. Iru won ni Sara ti o gbọran si Abrahamu lẹnu ti o pe e ni “oluwa mi”.”
Iwe Jẹnẹsisi (16: 3): “Leyin naa Olohun wi fun obirin naa pe: “N óo fi kun inira re nigba ti o balóyún, ninu irora ni o óo maa bímọ. Sibẹsibe, lọdọ ọko re ni ifẹ re yoo maa fa si, oun ni yoo si maa se olori rẹ.”
9). Jiju obirin alagbere loko titi yio fi ku:
Iwe Dieteronomy (13: 22): “Bi enikan ba gbe omoge niyawo, sugbon ti o korira re leyin ti o ti ba a lopọ, ti o wa so pe o ti se isekuse, ti o si fi bee so o ni oruko buruku, ti o wa wi pe; Mo gbe obirin yii niyawo sugbon nigba ti mo sunmọ, nko ba a nile. Ki baba ati iya omobirin yii mu asọ ibale re jade, ki won si mu un tọ awon agbaagba ilu na lọ ni ẹnubode...Awon agbaagba ilu naa yoo mu okunrin yii, won yoo naa daradara, won yoo si gba ọgorun iwọn ṣekeli fadaka lọwo re fun baba omobirin na bii owo itanran,....Sugbon bi ẹsun ti won fi kan obirin naa ba je otito, pe won ko ba a nile, won yoo fa obirin na lọ si enu ona ile baba re, awon okunrin ilu yoo si sọ o ni okuta pa.”
Iwe Dieteronomy (22: 22): “Bi ọwo ba tẹ okunrin kan ni ibi ti o ti nba iyawo oniyawo lopọ, pipa ni ẹ gbodo pa awon mejeeji; ati okunrin ati obirin naa. Pelu eleyi ni won yio fi mu aburu kuro laarin yin.”
Iwe Dieteronomy (23: 22): “Ti okunrin kan ba ba odo-moge ti ko ti ri okunrin ri soro ife, ti okunrin naa wa ri ni arin-lu, ti o si ba a lopọ, ẹ mu awon mejeeji jade wa si enubode ilu, ki ẹ si sọ won ni okuta pa.”
10). Obirin wa ni ipo ti o kere si ti okunrin:
Iwe alakoko ti Bolisi ko si awon ara Korinti (3: 11): “Mo fe ki ẹ mọ pe Mesia ni ori fun olukuluku okunrin, okunrin ni ori fun obirin, Olohun wa ni ori Mesia. Okunrin ti o ba nsadura tabi ti o ba nwaasu ti o bo ori fi abuku kan ori re, sugbon obirin ti o ba nsadura tabi ti o ba nwaasu lai bo ori re fi abuku kan ori re, o dabi ki o kuku fa ori re, nitori bi obirin ko ba bo ori, ki o kuku ge irun re mọ le, sugbon ti o ba je itiju fun obirin lati ge irun re mọlẹ tabi lati fa ori re a je pe o ni lati bo ori re, ko leto fun okunrin lati bo ori re, nitori aworan ati ogo Olohun ni. Sugbon ogo okunrin ni obirin, nitori okunrin ko wa lati ara obirin; obirin ni o wa lati ara okunrin, atipe a ko da okunrin nitori obirin, obirin ni a da nitori okunrin. Nitori eyi, o ye ki obirin ni alasẹ ni ori re nitori awon angẹli.”
11). Awon ẹkọ Deskolia fun awon obirin:
Abawọle keji ninu Deskolia pelu akọle (o sọranyan fun awon obirin lati maa tẹri ba fun awon ọkọ won, ki won si maa dunnu si idajọ re) o nsọ bai pe: “Ki obirin ya maa tẹri ba fun ọko re toripe ori obirin ni ọko re,...Iwọ obirin yaa mọ paiya ọko re, ki o si maa tiju re, ki o si maa wa iyọnu re ni oun nikan soso lehin Olohun, gegebi a ti wi, se irọrun fun u nibi iranlọwọ re ki oko re naa le fa ọ mọra lọdọ re, ti o ba fe jẹ olugbagbọ ododo ati eniti Olohun yo yọnu si ma se maa ṣọṣọ lati baa mọ yọ awon okunrin àjojì ninu, ma se maa rankan lati wọ asọ ti awon enia yio fi ma nirankan si ọ tabi asọ fẹlẹfẹlẹ eleyi ti ko lẹto ju fun awon alagbere lọ ki awon eniti won ndẹdẹ iru awon olumura bai mọ ba moo tẹ le ọ. Ti o ba nbe ni eniti ki se iru awon iwa buruku iwa asise won yi, pelu ọṣọ re yi oun nikan ni ki o maa tẹba fun pelu oso re, toripe iwọ pelu eleyi; oo ma fitina awon eniti nwo e, ti won si ndede re, ki wa lo de ti ó o le para mọ ki o ma ba ko si inu asise yii, ki o si ma ba ko enikẹni si inu iyemeji tabi owú nitori ti ẹ, nigbati o ba se asise pelu mimọọmọ se ìṣesí yii iwọ naa ó pada subu, toripe iwo ni óo je okunfa fun kiko iparun ba ẹmi okunrin yi. Lẹyin na, nigbati o ba se asise lori enikan pelu ìṣesí yi ni ẹẹkan-soso, oun naa yio je okunfa nibi pe ki o sa sise lọdo ọpolopo enia, ti o si jẹ eni ti agbeele rẹ kere, gẹgẹbi iwe-mimọ ti nsọ pe: “Nigbati munafiki ba subu si inu awon aburu to pọ yio yẹpẹrẹ, yio si fa inira ati alebu fun un” gbogbo obirin kọọkan ti ba nse bai yo parun pelu asise yoo si maa dede e awọn ẹmi awon alaimọkan lai nidi. Ki o ya lọ mọ ohun ti iwe-mimọ sọ fun eni ti nda adapa irọ mọ awon eniti won nbe lori eleyi pelu ọrọ pe: “Won korira obirin bu ju iku lọ, eleyi ni eyi ti o jẹ panpẹ fun awon alaimọkan” Bakanna ni aaye mii o nsọ pe: “apejuwe bi ikan se ma njẹ igi, gẹgẹbe ni obirin bu se ma nko iparun ba ọkọ re” o tun nsọ bakanna pe: “O dara; ibugbe ti o ba nbẹ ni koro ni ori aja lọla ju gbigbe pọ pelu obirin odale lo”. Ẹ mọ fara we awon obirin eleyi, ẹyin obirin elesin mesia ti ẹ ba fe je onigbagbọ lododo, ni akolekan pẹlu ọko re ki o si maa wa iyọnu re ni oun nikan soso. Ti o ba nlọ loju ọna bo ori re pelu iborun re, nitori ti o ba ti bo ori re pelu aso itiju oni idabo-bo kuro nibi oju awon ẹni buruku, mọ se mo se ọṣọ si oju re ti Olohun da fun ọ, kosi nkan ti o le din ẹwa ibẹ ku, tori gbogbo ohun ti Olohun da ni o rewa gan, ko ni bukata si ọṣọ, nitori gbogbo ohun ti won ba ti le kun lori dídára yoo ma yi idẹkun Oba adeda pada ni, ti o ba nrin ki oju re o maa wo ilẹ, ki o si bo ara re ni gbogbo agbegbe, jina si ọre ayo ti ko lẹtọ pelu awon okunrin, ti í si ma nkopa ni opolopo igba nibi awon iwa pooki. Obirin onigbagbọ ododo kii mu awon okunrin ni aayo, ti o ba si bo oju re yio bo pelu iberu lati ma ba maa wo awon okunrin àjojì,...Eleyi ti o je oranyan fun ọ ti o ba je olugbagbọ ododo ni ki o maa sa fun gbogbo iran ohun ti ko ni anfani ninu, ati mima wo awon oju lọpolọpo...(Dajudaju ima gbe inu papa loore ju gbigbe pẹlu obirin alahọn gungun alaigbọran lọ).”

Niná obirin ni awon awujọ awon Nasara iwọ-ooru (Gẹẹsi)
Ọpolopo ninu awon ọta Islam ngbiyanju lati fọn awon iruju ka nipa Islam. Lara re ni alamori niná obirin, ti won nlo nibiyi amuga idan wọn ti won ba saaba, ti won yio mo mu ninu awon aaya Alqur’an alaponle ati lati inu awon Hadisi Ojisẹ - ki ike ati ola Olohun o maa ba a – oun ti yio ranwon lowo lori awon iruju won. Niná ninu Isilam, wọn yio so sanponna lai so pelu awon oun to ro po mo ni waju ati leyin ninu awon ọrọ lati le mo tan iruju-iro ka nipa Islam pelu ọgbọn-ẹwẹ buruku won ti ko wulo, to jina yanyan si otitọ ọrọ. Won ko ni akori oro ni pipe re, bi kii se pe won yio mu aworan die lara re ti yio mo wa sele pẹlu re agboye buruku lati se iranwọ fun won nibi awon adapa irọ won nipa Islam, ti won si npepe ape mora si odo ara won lori abalo daada pelu awon obirin ati awon iyawo won. Sugbon ni paapa won gboju kuro nibi awon otitọ ti nbọ yii:
Akọko: Dajudaju Islam ni ẹsin kan soso eleyi ti o tọka si ajọsepọ ifayabalẹ ati ifẹran laarin tọkọ-taya. Ohun na si ni ẹsin kan soso ti o kọ kikọja aala ati fifi suta kan- ni yala pẹlu ọro ni tabi pẹli ise, Olohun ti ola Re ga ju sọ bai pe:
Itumọ: (Atipe o mbẹ ninu awon ami re pe, O da awon aya fun nyin lati ara nyin ki ẹ le ba maa ri ifayabalẹ ati ifẹ lọdọ wọn.) Surotu Ar-ruum 21. Ni ti mimọ pe dajudaju ifayabalẹ ati ifẹran yii ko le e waye ayafi lati ara yigi ti o ni alaafia ti o si lẹtọ ti o ba ilana sharia mu.
Ẹẹkeji: Dajudaju Islam ni ẹsin kan soso eleyi ti o fagile niná obirin ati yiyẹpẹrẹ re ati mimaá fi oju abuku ati iyẹpẹrẹ wo ó lati ẹgbeje ọdun (1,400) ti o ti re kọ ja, ti o si ri eleyi gẹgẹbi abuku fun okunrin. Ti a ba se iwadi ninu iwe mimọ awon Nasara yala majẹmu lailai ni tabi majẹmu tuntun a ko nií ri itọkasi kan nibẹ ni eyi ti o sunmọ tabi eyi ti o jina nibi sise niná obirin leewọ.
Ẹẹkẹta: Dajudaju Islam se’ni loju kokoro lori ibalo ti o dara pẹlu obirin, gbogbo awon aaya Alqur’an ati awon hadisi abiyi ti oó nii se pẹlu ajọsepọ lọkọ-laya apakan won pelu apakan ń s’eni loju kokoro lori ibasepọ to rẹwa ati sise daada larin oko ati iyawo, apakan won si apakeji. Olohun ti ola Re ga ju lọ nsọ bai pe:
Itumọ: (O wa fun awon obirin lori ọkọ iru ohun ti o wa fun ọkọ lori won pelu daada) Surotu Al-baqarọh: 228.
Ẹẹkẹrin: Dajudaju Islam se awon ajọsepọ omo-enia paapa julo larin ọko ati iyawo ninu awon okunfa lati ri ẹsan daada ati laada lodo Olohun. Ojise Olohun- ki ikẹ ati ọla Olohun o maa ba á – nsọ bai pe: “Óo nií maa ná níná kan lati fi wa oju rere Olohun ayafi ki Olohun o san ọ lẹsan pelu rẹ, titi ti o fi mọ okele ti o nfi sẹnu obirin rẹ.” Won f’ẹnu ko le lori.
Ẹẹkarun: Dajudaju Islam se biba obirin wi lẹtọ gẹgẹbi ayafi ti kii se gegẹbi ipilẹ, ati labẹ awon majẹmu ti yio kọdi ọkọ nibi lilọ si ibi lulu gẹgẹbii ona-abayo, ayafi nigbati ko ba si ona abayo kankan mo fun lati ti aburu nu. Eleyi ni pe awon obirin ko si ni ori ìṣesí kan soso ni gbogbo asiko ati gbogbo awon awujọ ati awon idile. Ohun ti o seese ki o jẹ atunse fun awujọ kan, o le ma jẹ atunse fun awujọ miran, o tun seese ki o jẹ inira fun dipo ki o ṣàtúnṣe fun, ohun ti o ba je atunse fun bibalo pelu obirin kan le ma je atunse fun obirin miran ni awujo miran tabi ni asiko miran, gbogbo bi o ti wu ki o gbiyanju to lati fi ṣàtúnṣe re. Eleyi tun je lori kikenu Islam ati kikari re fun gbogbo ohun ti o seese ki o sẹlẹ.
Ẹẹkẹfa: Dajudaju alamori ija loko-laya inu ẹbi je oun ti fọnka gan ni ọpọlọpọ ilu. Melo melo okunrin kiristani iwọ-orun (gẹẹsi) ti o nfi suta kan iyawo re ni gbangba loju awon enia ni papa okọ ofurufu tabi ile ounjẹ tabi ni ile-ọti titi ti o fi mọ oju-ọna gbogbo enia loju awon ti won re kọja lọ. Eleyi kii se ohun ti o pamọ, koda o jẹ ohun ti won fi ntakurọsọ lori apakan awon irinsẹ ikede ti o jẹ alafihan tabi alafeti-gbọ. Bakanna melo melo obirin iwọ-orun (gẹẹsi) ni amẹrika ati kanada ati yirobu ati ọsirelia ti ngba agọ awon ọlọpa lọ lati fejo pe oko re sun lori pe onaa.

Titanka lulú ti o foju han ni awon awujọ iwọ-orun (gẹẹsi)
Lati salaye titanka ija loko-laya inu ebi ni iwọ-orun (gẹẹsi) eleyi ti npepe ọlaju ati idagba-soke ni nti boyii:
1). Titanka awon eto ati awon akojọ ti o jẹ ti ijọba ati eyi ti ki í se ti ijọba ni awon ilu Yurobu eleyi ti ndide si awon isoro fifi suta kan awon iyawo’le ati ilekoko inu ẹbi.
2). Awon ikede ti npara ni ori awon nkan igbohun safefe oni wiwo ati oni gbigbo, eleyi ti ngbe gbogbo ikoja aala awon ara adugbo lori iyawo alabagbe won ni kete isele naa.
3). Awon ibere won mo ndo ju re ko awon ara awujọ iwọ-orun (gẹẹsi) ni gbogbo-igba, ninu re ni:
* N jẹ o ti sẹlẹ si ọ ri pe ki o náa iyawo rẹ koda ki o jẹ ẹẹkan.?
* N jẹ o ri tabi gbọ ni ọjọ kan ti baba rẹ náa iya rẹ bi ?
* N jẹ o ti gbọ siwaju ri pe ọkan ninu awon ẹbi rẹ náa iyawo rẹ?
* Ń jẹ o ti gbọ siwaju ri pe ọkan ninu awon aladugbo rẹ náa iyawo rẹ ?
Ohun ti a gba lero nibi mimu awon ibere yii wa ko ju lati se afirinlẹ ifojuhan ifisuta kan awon iyawo-ile lati ọdo awon ọkọ won ti won jẹ elesin kristi ni gbogbo Yurobu ati Amẹrika ati Kanada ati Ọsirelia. Eleyi je ohun ti ofojuhan ti osi gbajugbaja ni awujo yii.
Nipari, yio han si gbogbo olooto enia, ọla Islam gbe fun obirin, atipe ohun ni ẹsin kansoso ti o gbọla fun un, ti o si gbe ipo re ga, ti o si se agbega fun un kuro lọdọ gbogbo ẹniti o ba fẹẹ ba apọnle rẹ jẹ, ti o si sọ ọmọluabi rẹ, ti o si se ikilọ ni ikilọ ti o lagbara lori sisabosi rẹ. Ojis Olohun- ki ikẹ ati ọla Olohun o maa ba a- ń sọ bai pe:”Mo ń se ikilọ fun nyin nibi ẹtọ awon ọlẹ meji; ọmọ-orukan ati obirin.” Ahmod ati An-nasai ati Ibnu majah ati ninu sohihi jamiu 2447.

 

Ìparí

Dajudaju Islam je ifiran gbere lati ọdo Olohun ti o fi ransẹ si awon ẹda pata lati ori ahọn Anabi Muhammadu – ki ike ati ola Olohun o maa ba a -. Paapa Ifiran atọdọ Ọlohun wa yii gbe ola fun omo-enia lati igba akọko ti o ti sọ kalẹ ọla lori ńkan miran ninu awon ẹda ti Ọlohun da. Olohun ti ola Re ga ju lọ sọ bai pe:
Itumọ: (Atipe dajudaju Awa se aponle fun awon ọmọ (Annabi) Adamọ, Awa nge won (rin) lori ilẹ ati odo, Awa si nfun won ni ijẹ-imu ninu awon ohun ti o dara, Awa si da wọn lọla ju ọpolọpo ninu awon ẹda ti A da lọ niti ọla.)Surotu Al’isroi 70.
Lehin sisafihan Olohun (Oba afọmọ Oba ti ola rẹ ga ju) fun enia pataki re, atipe o jẹ eniti owun gbọla fun lori ọpolopọ ninu awon ẹda, O wa kede opo miran; ohun ni opo deede larin gbogbo ẹda nibi ipile isẹda won. Olohun ti ola Re ga ju lọ sọ bai pe:
Itumọ: (Ẹyin ọmọ-enia ẹ paiya Olohun Ọba yin, Ẹni ti o sẹda nyin lati ara ẹmi kan soso) Surotu An-nisai 1.
Lati ibi koko ipilẹ yii omo-enia yio se deede pelu omọ-enia miran nibi pataki ijọmọ-enia, onikuluku loni anfani lati se agbekalẹ ọrọ tabi lati mu irori wa tabi lati se anfani pelu ohun ti Olohun fi sinu aiye yii ninu awon idẹkun ati awon oore, koda kosepe opinya tabi iyato wa larin won. kii se lori iyapa nibi iran abi awọ abi ipilẹṣẹ, koda ki won yapa si ara won ni ipo ise aye, ko si gbigbọla fun lati ọdo Olohun lori iyapa ẹya tabi awọ tabi ipilẹsẹ. Gbogbo omo-enia lọdọ Ọlohun bakanńa ni won; akọ ni tabi abo, olowo tabi alaini, abiyi tabi ẹni yẹpẹrẹ, sugbon iyatọ yio mo wa larin won pelu odiwọn jijana won ati sisunmọ won nibi lilo ofin Sharia Ọlohun ati diduro deede lori oju-ọna re ti o dara. Olohun ti ola Re ga ju lọ so bai ni Ẹni ti nba awon enia sọrọ ti ń salaye ipilẹ ti o tobi yii fun won pe:
Itumọ: (Enyin enia dajudaju A da yin lati ara okunrin ati obirin, A si se nyin ni orilẹ-ede ati iran-iran ki ẹ le baa maa mọ ara nyin, dajudaju ẹni ti o ni ọla ju lọdọ Ọlohun ninu nyin ni ẹni ti o paiya (Rẹ) ju.) Surotu al’hujurooti 13.
Awon ẹko Islam gbe omọ-enia pelu ọmọ-enia miran si ipo kanna nibi ipile iṣẹda ati pataki ọmọ-enia, o se obirin ni deede si okunrin nibi gbogbo nkan yatọ si nibi ohun ti bukata ti o foju han ba pepe fun lọ sibi sisayafi rẹ. Ọlohun ti ola Re ga ju nsọ bai pe:
Itumọ: (Onigbagbọ ododo okunrin ati onigbagbọ ododo obirin apakan won jẹ ọrẹ apakeeji) Surotu at-taubah 71.
Ọlohun ti ola Re ga ju lọ tun so bai pe:
Itumọ; (Oluwa won si jẹ ipe won pe: Emi ki yoo pa iṣẹ oṣiṣẹ kan ninu nyin ladanu ni okunrin tabi obirin) Surotu aali imron 195.
O see se ki o jẹ ninu ohun odara ni ki a mu enu ba die ninu oun to wa sinu lakai ni soki:-
* O rọru lati sọ ninu oun ti mo ni amodaju re pe dajudaju obirin ko ni, kosi leni igbadun ati ominira pẹlu awon ẹtọ re lailai ayafi ni abẹ onbirela esin Islam, nitori ó jẹ ẹsin sanmọ, ti Olohun Ọba adeda gbe kalẹ, ti o da akọ ati abo, ti o ni mimọ ohun ti o dara fun awon ìṣesí wọn ni aiye won ati ni ọjọ ikẹhin won.
* Ko lẹtọ ki a ma se idajọ lori esin Islam latara oun ti a nri lodo apakan awon musulumi, tori ọpọlọpọ awon ti won ń se afiti ara won si inu Islam ko si ninu Islam rara nibi nkankan nitoripe Islam kii se eri jijẹ mejeeji nikan lasan, bi kii se pe o jẹ adiọkan ati fifi sisẹ se. Ni apejuwe a ri ninu awon musulumi ẹni ti nparọ, ti njanba, ti si nse apakan awon iṣẹ bú. kii se itumọ eleyi ni pe Islam npasẹ rẹ tabi se afirinlẹ rẹ !!! Islam jẹ iho kan ti o tobi, o nbẹ ninu awon musulumi ti í ma nlo gbogbo ẹkọ rẹ lati de ipo pipé, o si nbẹ ninu won ti yio maa se aṣètò leyi ti yio maa kosi inu apakan awon iyapa si ofin Olohun, eleyi ti o lẹtọ ki o jiya lori rẹ yala ni ile-aiye tabi ni ọjọ ikẹhin, sugbon ko ni kuro ninu jije Musulumi, oun ni eni ti won ma ń lo musulumi ẹlẹṣẹ tabi oludẹṣẹ fun.
* Ipepe kan ti maa doju re kọ eni kọọkan ti ki se musulumi ni pe ki ominira o maa bẹ fun nibi idajọ re lai je olutẹle ẹlomiran nibi ironusi ati adojukọ rẹ. Atipe ki o ká nipa Islam ninu awon iwe ti won ni oorin ti won si won si ni ifọkan-tan ninu won, ki o le baa mọ latarare nipa Islam ati eto rẹ, nitoripe ẹsin Ọlohun ni. Eniti o ba ka nipa esin yii pelu jijina si igbarata ẹsin ati ẹyamẹya lati fi wa ododo, mo jẹ onifayabalẹ pelu iyọnda Ọlohun pe dajudaju Ọlohun Ọba yio fi imọlẹ si oju ona rẹ yio si fi mọ ọna to tọ fun ẹni ti Ọlohun ba fẹ daada fun.
Olukọwe lobirin (L. Vaglieri) 124, nsọ bai ninu iwe rẹ lati se idaabobo Islam pẹlu pe kii se musulumi: " Ni jijina si itanjẹ pẹlu iwa buburu ati tita abajade re sọnu, opondandan fun obirin musulumọ lati lo jẹlibaba, ki o si bo ara rẹ pata yatọ si awon orikerike ti won yonda fun pọmbele gẹgẹbi oju mejeeji ati gigisẹ mejeeji. Eleyi kii se latara kikere apọnle fun obirin tabi lati ba erongba won jẹ, a mọ bi kii se lati sọ won kuro nibi lowo okunrin, eleyi ni ofin ipilẹ ati jo un ti won fi ya obirin kuro larin awon okunrin ati iwa rere ti o jade lati ara rẹ ni eyi ti o le sọ okowo awon ọlọtẹ di ofo ni awon ilu ila-orun ayafi ni awon agbegbe ti awon ajoji ba ti ńi ipo ati aṣẹ, nigba ti eni kẹni ko ba ti ni ìkápá lati ta ko pataki kikojọ yi, yio wa han si wa lati se àmújáde pe ìṣesí piparamọ obirin jẹ ipilẹ ti o sanfani, ti kii se pe ń pawo wọle fun awujọ Islam.
Ni igbẹhin adua wa ni pe: Ọpẹ ni fun Ọlohun Oluwa gbogbo ẹda.

www.islamland.com