IRORUN ESIN ISLAM

IRORUN ESIN ISLAM

IRORUN ESIN ISLAM
سماحة الإسلام باللغة اليوروبا

 


Dr. Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة


Itumo ni ede Yoruba
European Islamic Research Center (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Ridwan Allah Murtadho
Atunto
Abd Ar-Razzaq Isa
 

www.islamland.com

NI ORUKO OLOHUN, OBA AJOKE AYE, ASAKE ORUN
ORO ISAAJU
Ope ni fun Olohun, ike ati ola ki o ma ba Anabi, ati awon ara ile re ati awon omoleyin re (As sahabah).
 Nigba ti awon eniyan bere si ni fi esun igbe sumomi kan esin Islam pupo, ti won si nse afiti awon iroyin ti ki se tire si odo re, leyi ti won gbero lati fi le awon eniyan seyin nibi esin Islam. Won se eleyi nitori bi onka pupo ninu awon eniyan se nwo inu esin naa. Bayi ni orisirisi ifesunkan ati iruju ti ko lese nle, ti ko si ni ododo kankan ninu bere si ni njade, ti o si jepe eleyi ko je nkankan ju alaye ti o duro lori iwoye ota esin Islam ati awon musulumi lo. Nitori idi eyi, ni aafa agba (As sheikh) Muhammad Sayfudeen, ti o je oludari fun Ogba ikeko esin Islam ati asa (olaju) re ti o wa ni ilu Braunschweig ni iluJamani (Germany) fi beere fun ki ko iwe kekere kan ti yoo so nipa Irorun Esin Islam. Eni ti o ni ola lori jijade iwe yi leyin Olohun Oba ti ola Re ga naa ni aafa agba yi.
 Isesi yi je iyalenu fun mi pupo, pataki julo lati ilu Jamani (Germany), toripe oun ti mo mo nipa awon ara ilu Jamani (Germany) lai ruju rara nipe won je awujo kan ti o dara niwa pupo, bakan naa bi o ba tun se wa nmo won siwaju si ni daadaa won ma nlekun si. Mo so oro yi latara asepo mi pelu opolopo lati ilu Jamani (Germany), yala awon ti won wa sise ni ilu wa ni tabi awon olutaja ninu won. Niwonba igba ti awon omo ilu je eniyan rere bayi ajepe ijoba ilu naa yoo je eyi ti o dara, nitoripe awujo ti o dara ko ni sesa ayafi olori ti o dara. Bakan naa eleyi foju han latara iduro deedee ti ijoba ilu Jamani (Germany) ma nduro lori opolopo awon isele agbaye.
Mo wa nki awujo ile Jamani (Germany) ku orire lori ijoba rere ti o ni, bakan naa mo nki ijoba ile Jamani (Germany) ku orire lori awujo rere ti o ni. Mo ni ife ilu Jamani (Germany) tokantokan, mo si ngbero ki daadaa, ilosiwaju ati idagbasoke ma de ba. Mo si nfiwon lokan bale wipe esin Islam ododo ko si fun nkankan ju ife ati ilalafia awujo lo, eyi ti yoo si foju han gbangba nibi kika iwe yi. Mo si nrankan lati odo ijoba ati awon ara ilu (Germany) pe ki won ronu daradara lori sisesa ati kikun esin Islam ododo ni igbunwo, ati sise afihan re ni ona ti o dara loju awon eniyan.
Eleyi ni ireti wa lati odo won si esin Islam, toripe ki won ba se bayi ni yoo mu atunse ba awoju won ni abala awon rogbodiyan ti won ko si latara olaju igbalode ti o se okunfa gbigbajumo lilo awon oogun oloro, gbigbajumo iwa ibaje orisirisi, iseya se baba, didaru molebi ati beebee lo. Bakan naa yoo tun se atunse eto oro aje won latara lilo eto inawo (esin Islam) ti ko mo oun ti won npe ni idenukole eto owo tabi iyipada eto oro aje ti o mu inira dani gegebi eyi ti nsele ni agbaye loni. Ipepe eyi ti opolopo ninu awon orilede agbaye npe lo sibi lilo ilana eto oro aye ti esin Islam naa to leri lori eleyi. Bakan naa ni abala eto oselu, won yoo ri iduroti eniyan ti o se deedee egbegberun lona egberun kan le etadin logota egbegberun (1.57billion) musulumi, onka ti o se deedee idakan ninu ida merin gbogbo aye, bakan naa won yoo ri ajosepo, ti o lagbara ti yoo si se ilu Jamani (Germany) ni anfaani, lati odo oun ti o to ida aadorun ninu ilu musulumi.
 Ako sope ko si ninu musulumi awon ti wonnfi isesi won ko abuku ba esin Islam yala won gbero bee tabi o seesi. Sugbon eyi ti o je deedee ni wipe ko leto ki a fi asise tabi iwa aito awon kan ninu awon musulumi ti sara esin Islam, nigba ti o si je pe awon isesi wonyi tako oju ona esin Islam paapaa. Ni ipari, mo nso ni ti ododo wipe mo nife Jamani (Germany) ati awon eniyan re. Itoka lori eleyi ni idahun mi kiakia si ibeere Aafa agba (As sheikh) Muhammad Sayfudeen, eyi ti mo si nki ilu Jamani ku orire lori riri irufe enia bayi laarin won, toripe o je onideede eniyan lori ipepe re, olododo nibi irori ati ilana re, ti o si ni akomona ti o yanju, ti o si tun je olufokansin ati ololufe ilu re pelu awon ara ilu naa. Eleyi ni ero wa lori re sugbon Olohun mo juwa lo.
NI ORUKO OLOHUN, OBA AJOKE AYE, ASAKE ORUN
 Open ni fun Olohun, ike ati ola Re ki o ma ba Anabi Muhammad, ati awon ara ile re ati awon omoleyin (As sahaba) re.
Dajudaju ninu awon okunfa ti o ran fifanka esin Islam lowo, ti o si je ki o je atewogba lodo awon ti kii se elesin Islam, ni gbigbajumo re pelu irorun agboye, irorun ilana re ati irorun nibi ajosepo pelu aitako adamo ipile ti Olohun da omoniyan le lori. Bakan naa ipepe re se deedee adamo omoniyan ti ko si tako o rara, eleyi wa ni ibamu si oro Olohun ti o sope:
" فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا فِطْرَتَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا لا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللَّهِ ذَلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لا يَعْلَمُونَ"
'' Nitori naa da oju re ko esin ododo (ni eni ti o duro deedee lori re) adamo Olohun ti O da omoniyan le lori, kosi ayipada ninu adamo Olohun, eyi ni esin ti o duro deedee, sugbon opolopo awon eniyan ko mo '' Q30:30.
Ninu awon apere ti a fi salaye eleyi ni adamo ibalopo (laarin okunrin ati obinrin), esin Islam ko ri si oun elegbin bakan naa nipe ko se ni eewo, biko sepe o tun pase gbigbo bukata naa ni kiakia, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَأَنْكِحُوا الأَيَامَى مِنْكُمْ وَالصَّالِحِينَ مِنْ عِبَادِكُمْ وَإِمَائِكُمْ إِنْ يَكُونُوا فُقَرَاءَ يُغْنِهِمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ "
'' Atipe ki e fe iyawo fun awon apon inu yin, ati awon eniyan rere l'okunrin ninu awon erukunrin yin ati awon erubinrin yin, ti won ba je alaini Olohun yoo ro won loro ninu ola Re, atipe Olohun ni Olugbaye Onimimo '' Q24:32.
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se ni lojukokoro ki a tete se igbeyawo ninu oro re ti o so bayi pe:
" يا معشر الشباب، من استطاع الباءة فليتزوج، فإنه أغض للبصر وأحصن للفرج، ومن لم يستطع فعليه بالصوم، فإنه له وجاء."
'' eyin odo, enikeni ti o ba ni ikapani ninu yin, ki o ya lo se igbeyawo, toripe o ma je ki a le reju (eni) sile, o si ma nje ki a le so abe (eni) (nibi agbere), eni ti ko ba wa ni ikapa ko ya ma gba awe, toripe yoo je iso fun un (Al Bukhari).
 Ni idakeji, esin Islam ko se ni oun eto ti ko ni mojemu tabi onde, sugbon o f'eto si, o si salaye ona ti o ye, ti o si to lati se isesi naa. O se igbeyawo ni onakan gbogi fun isesi naa. Latara igbeyawo ni ifokanbale ti o fese rinle, eyi ti gbogbo wa nsare fun, fi le waye, latara re naa sini ifera eni denu ti o ma nje ki ajogbepo lailai ma be laarin loko laya fi le sele, eyi ti o si ma nje ki awon omo waye laarin awon mejeeji, ti okan ikinni keji won yoo si bale lori eso ti o ba waye latara rinrin oju ona Olohun ati asopo ti o mo yi. Eleyi ni Olohun salaye pelu oro re wipe:
" وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُمْ مِنْ أَنْفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُمْ مَوَدَّةً وَرَحْمَةً إِنَّ فِي ذَلِكَ لآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ "
'' Atipe o nbe ninu awon ami Re pe O da awon aya fun yin lati ara yin, ki e le ba ma ri ifayabale lodo won, O si se ife ati ike si aarin yin. Dajudaju awon ami nbe ninu eleyi fun awon eniyan ti o nronu '' Q30:21.
 O se awon ona miran ti o yato si eleyi ni eewo, o si se ikilo lori re, nitori awon oun ti yoo ti eyin re yo gegebi ajakale aisan, gige okun mimo bi si ati mimo re si ati bibi awon omo ale (agbere) ti won yoo je elemi lile, oni iwabaje ati olugbogun ti awujo won. Olohun Oba ti ola Re ga so bayi pe:
 "وَلَا تَقْرَبُوا الزِّنَا إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَسَاءَ سَبِيلًا "
'' Ati ki e ma si se sunmo agbere (zina), dajudaju o je iwa aimo, o si buru ni oju ona '' Q17:31.
 Esin Islam ko se igbeyawo laarin loko laya leyi ti ko lopin nigba ti okan ninu awon toko taya ba se afeku ife enikeji re, esin Islam se ni eto pe ki won ko ara won sile ni ibamu si ilana ti ko ra eto enikankan lare ninu awon mejeeji, ti o si se amojuto igbonmo won. Toripe eyi ti o je afojusun esin Islam ni lati gbe idile alayo kale, eyi ti yoo je ipile fun gbigbe dide awujo ti o dara, eyi ti yoo si je okunfa ki enikookan ninu awujo le se esin ati igbesi aye re pelu ominira ati irorun, ti yoo si di eni ti o ni aseyori nibi adawole re.
 Bayi ni o se ri ninu gbogbo alamori oun adamo omoniyan. Ilana ofin Olohun wa lori sise ede ati irora, bakan naa lati mo la bo orun omoniyan oun ti ko lagbara re, yala ninu ise sise ni tabi oro siso. Pelu eleyi ni ododo ni esin Islam je esin ikeyin, eyi ti Olohun Oba mimo Oba ti ola Re ga, sa lesa pe ki o je esin gbogbo agbaye patapata. Eni ti o fe gba ni esin, o si wa se orire aye pelu nini ifokanbale emi ati ibale okan, eyi ti ko le han si enikankan ayafi eniti o ba ngbe pelu adun igbagbo ododo, ti o si tun nreti orire ti orun, pelu iyonda Olohun ti ola Re ga, eyi ti se ogba idera ti ibu re da gegebi ibu sanmo ati ile, eyi ti won pese re fun awon olupaya Olohun. Eyi ti Olohun si se ni eewo fun awon ti O se l'eewo fun, ni ibamu si ogbon Olohun ati deedee Re. Iru eniyan bayi yoo gbe igbesi aye inira ati ifun pinpin nile aye, koda ko sepe oun ti o foju han nipe olorire ni l'aye, ti o si jepe oun ti o nreti re l'orun je iya lailai ti ole koko. Ki Olohun so wa nibe.
 Nigba ti o je pe iroyin ipile fun omoniya ni adinku ati aseeto, eleyi lo fi jepe esin Islam ni eyi ti o se amojukuro fun omoniyan ni pataki julo nibi adinku re nibi oun ti o je mo iwo Olohun Oba ti O mo, Oba ti ola Re ga. Toripe iwo Olohun je eyi ti o wa lori ipile amojukuro, aanu ati aforijin. Amojukoro yi ati aanu pelu aforijin wa fun gbogbo iwo Olohun patapata, ayafi nibi iwo Olohun kan soso ti se imu Olohun ni okan soso ati nibi jije eru fun Olohun nikan soso. Iwo yi je eyi ti Olohun ko yonu si ki enikankan ba Oun ni ipin nibe tabi ki a wa fi sori elomiran leyin Re. Eleyi si ni O salaye ninu oro Re wipe:
"إِنَّ اللَّهَ لَا يَغْفِرُ أَنْ يُشْرَكَ بِهِ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَلِكَ لِمَنْ يَشَاءُ "
'' dajudaju Olohun ki yoo se aforijin fun eniti o ba pa nkankan po mo O, sugbon yoo aforijin ese miran ti o yato si eyi fun enikeni ti o ba fe,..'' Q4:48.
Esin Islam fi ona abayo lele lori eyikeyi asise tabi ese ti eniyan ba da. O ba lakaye omoniyan soro, o si wa iwosan si idamu emi re pelu gbigbe ilana ironupiwada kale fun lati le kuro ni idi ese. O se bibanuje lori ese ni okunfa ipare ese naa. Olohun je Olutore Alanu, leyin ti O ba fori jin omoniyan tan lori ese re yoo tun san lesan lati odo Re, toripe o gbe ese ju sile nitori iberu Olohun, atipe o tun nrankan oun (oore) ti nbe lodo Re. Ewo ninu daadaa lo fi ndabi eleyi? Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
 "قُلْ يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ أَسْرَفُوا عَلَى أَنْفُسِهِمْ لَا تَقْنَطُوا مِنْ رَحْمَةِ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ جَمِيعًا "
'' Sope: eyin erusin mi ti e d'ese bo emi yin (lorun), e ma so ireti nu nipa ike Olohun, dajudaju Olohun ma nse aforijin gbogbo ese patapata.. '' Q39:53.
Esin Islam se ilana ironupiwada (At awbah) ni irorun fun awon eniyan, o si se ni oun ti o rorun ti ko si inira tabi idamu nibe rara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَمَنْ يَعْمَلْ سُوءًا أَوْ يَظْلِمْ نَفْسَهُ ثُمَّ يَسْتَغْفِرِ اللَّهَ يَجِدِ اللَّهَ غَفُورًا رَحِيمًا "
'' Enikeni ti o ba nse ise aburu kan tabi o nse abosi emi ara re, leyin naa ti o wa wa aforijin lodo Olohun, yoo ba Olohun ni Alaforijin Alanu '' Q4:110.
Olohun ti ola Re gat un so bayi pe:
"وَهُوَ الَّذِي يَقْبَلُ التَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِ وَيَعْفُو عَنِ السَّيِّئَاتِ وَيَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ "
'' Oun ni eni ti o ma ngba ironupiwada awon erusin Re, atipe O si nse amojukoro nibi awon asise, atipe O mo oun tie yin nse '' Q42:25.
Esin Islam ni akolekan emi omoniyan pupo, eyi (emi) ti asise lore kore po pelu mimo da awon ese ati iyapa ase Olohun. O wa se aforijin Re ni eyi ti o ni asepo pelu ironupiwada (At tawbah) kuro nibi ese naa bio tile wu ki iyapa naa ma para to. Ni ibamu si bi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti salaye ninu oro re wipe:
 " إن الشيطان قال: وعزتك يا رب لا أبرح أغوي عبادك مادامت أرواحهم في أجسادهم فقال الرب:" وعزتي وجلالي لا أزال أغفر لهم ما استغفروني"
'' dajudaju esu so bayi pe: mo fi iyi re bura, Oluwa mi, mi o ni ye leni ti yoo ma tan awon erusin re (omoniyan) je ti ma si siwon lona (pelu iwa ibaje) niwonba igba ti emi ba si nbe lara won, Olohun si dahun wipe: mo fi iyi mi ati gbigbongbon mi bura wipe mi o ni ye fori jinwon niwonba igba ti won ti ba nwami ni alaforijin '' (Ahmad)
Bakan naa ni o tun se aforijin fun eyikeyi ese tabi asise ti omoniyan ba se latara ijeninpa, asise tabi igbagbe, leyi ti ko gbero lati se, ti ko si taku sori re. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
« إِنَّ اللَّهَ تَجَاوَزَ عَنْ أُمَّتِى الْخَطَأَ وَالنِّسْيَانَ وَمَا اسْتُكْرِهُوا عَلَيْهِ ».
'' dajudaju Olohun ti se aforijin fun awon ijo mi lori (oun ti won ba se latara) asise tabi igbagbe tabi oun ti won ba je won nipa le lori '' (Ibn Majah).
Ninu Islam, ilekun aforijin wa ni sisi sile ni gbogbo igba ati ni gbogbo ipo kipo ti eniyan ko ba wa, koda ko ku die ti omoniyan yoo kuro laye, ko ni se pelu asiko tabi aaye rara. Olohun Oba ti ola Re ga so bayi pe:
" إِنَّمَا التَّوْبَةُ عَلَى اللَّهِ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السُّوءَ بِجَهَالَةٍ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِنْ قَرِيبٍ فَأُولَئِكَ يَتُوبُ اللَّهُ عَلَيْهِمْ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًاوَلَيْسَتِ التَّوْبَةُ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ حَتَّى إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ إِنِّي تُبْتُ الآنَ وَلا الَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمْ كُفَّارٌ أُولَئِكَ أَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا "
''Ironupiwada ti Olohun ma ngba ni ti awon ti won fi aimokan se ise aburu, leyin naa ti won ronupiwada laipe. Awon wonyi ni awon ti Olohun yoo gba ironupiwada won, Olohun si je Olumo Ologbon \\ ko si igba ironupiwada fun awon ti won se aburu ti iku fi de ba okookan won, (nigba yi) ti o wa nsope emi ronupiwada nisinsin yi, beeni ko si fun awon eni ti won ku si ipo keferi, awon wonyi ni a ti pese iya eleta elero sile fun'' Q4:17-18.
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إن الله عز وجل ليقبل توبة العبد مالم يغرغر "
'' dajudaju Olohun Oba abiyi Oba ti o gbongbon, yoo ma gba ironupiwada erusin (re) nigba ti ko ba ti mo pokaka iku '' (Ahmad).
Ko si iso ireti nu nibi ike ati aforijin Olohun ninu esin Islam. Esin Islam ko ima so ireti nu nibi aanu ati aforijin Olohun, o si ka si isesi awon keferi oluko tOlohun. Olohun ti ola re ga so bayi pe:
: "إِنَّهُ لَا يَيْأَسُ مِنْ رَوْحِ اللَّهِ إِلَّا الْقَوْمُ الْكَافِرُونَ "
'' Dajudaju enikeni ko ni so ireti nu nipa ike Olohun, ayafi (awon) ijo alaigbagbo ''Q12:87.
Toripe aforijin yoo ma sele si eru pelu idera Olohun (lori re) nigba ti o ba ronupiwada ati nigba ti o ba toro aforijin. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
« وَالَّذِى نَفْسِى بِيَدِهِ لَوْ لَمْ تُذْنِبُوا لَذَهَبَ اللَّهُ بِكُمْ وَلَجَاءَ بِقَوْمٍ يُذْنِبُونَ فَيَسْتَغْفِرُونَ اللَّهَ فَيَغْفِرُ لَهُمْ ».
'' mo fi eni ti emi mi nbe lowo re bura, ti e ko ba ma dese ni, Olohun ko ba mu yin kuro (lori ile), iba si mu awon miran wa ti won yoo ma dese, ti won yoo si ma wa Olohun ni Alaforijin, ti yoo si ma forijin won '' (Muslim).
 Bakan naa, esin Islam si ilekun irankan (s'odo Olohun) sile, o sise ronupiwada ati wiwa tutuba kuro nibi iwa ese ni oun ti Olohun nferan ti O si nyonu si, ti O si ma ndunnu lori re pelu. Eleyi si je okunfa ki eru tete ronupiwada lori ese re. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:
" الله أشد فرحا بتوبة عبده المؤمن من رجل في أرض دوية مهلكة. معه راحلته. عليها طعامه وشرابه. فنام فاستيقظ وقد ذهبت. فطلبها حتى أدركه العطش. ثم قال: أرجع إلى مكاني الذي كنت فيه. فأنام حتى أموت. فوضع رأسه على ساعده ليموت. فاستيقظ وعنده راحلته وعليها زاده طعامه وشرابه. فالله أشد فرحا بتوبة العبد المؤمن من هذا براحلته وزاده."
'' Olohun ma ndunnu lori ironupiwada erusin re ti o je olugbagbo ododo ju bi arakunrin kan ti o wa ni ile-asale (aginju) (ni eni ti nreti) iparun. Ti o jepe o ko oun jije ati mimu re sori nkan igun re, l'oba sun lo, sugbon nigba ti o ji nkan igun re ti lo (sonu). O wa titi ongbe fi bere si ni gbe e. leyin naa ni o sope: je ki npada si ibi ti mo wa tele, ki nsun sibe ki iku fi de. O gbe ori re le owo re leni ti nreti iku. Sugbon nigba ti o ji pada, o ri nkan gun re ni egbe re leyi ti awon oun jije ati mimu re nbe lori re! inu Olohun ma ndun si ironupiwada erusin re ti o je olugbagbo ododo ju (idunnu ti nbe fun) arakunrin yi (ti o ri) nkan igun re pelu onje ati omi re pada ''(Muslim).
 Latara kika iwe kekere yi, yoo han si o gbangba, ti o si mo opolopo nipa bi esin Islam sese amojuto eto irorun ati irora ninu gbogbo abala eto isemi aye, yala eyi ti o ni nse pelu enikookan ninu awujo ni, tabi eyi ti o ni nse pelu akojopo eniyan, lori oro aye ni tabi oro esin. Jowo fi die sile ninu asiko re lati ko tabi lati mo nipa esin Islam, ma se je ki isesi awon alaimokan tabi awon eniyan ti ko leko esin ninu musulumi je ipile fun idajo re lori esin Islam. Ti o ba te o lorun ti o si gba a, orire ni Olohun fi ta o lore, ti o ko ba si gba a, ajepe alekun imo ti nbe fun o ati aworan ti o je ododo nipa esin Islam, eyi ti yoo gbe iruju ati idarudapo ti awon ota esin nlo lati gbogun ti esin kuro fun o.
 Ki o si lo mo pe dajudaju eyikeyi nkan ti o ba ti tako adamo ti o ni alafia ati lakaye ti o pe ko si lara esin Islam. Oun iyanu nla ni ki awon eniyan kan ma lo sotun sosi lati se iwadi nipa esin ti o le mu won sorire, ki won wa lo se esa esin ti o tako lakaye ti o pe tabi adamo ti o ni alafia, koda ti emi ti o ni alafia naa tun ko, ti won si pa esin ododo ti. Oun ti o si se okunfa eleyi ni esu ti o ti gbero lati so omoniyan nu, ki o si dari won kuro loju ona esin ododo. Eyi ti o mo wipe ti won ba fi le tele oun, won yoo kodi won kuro nibi olorire ni aye ati orun. Eleyi si ni adehun ti o se ni ojo ti won yo o jade ti won si le (kuro ninu ogba idera). Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قَالَ فَبِعِزَّتِكَ لَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ الْمُخْلَصِينَ "
'' (Esu) sope: pelu agbara Re, dajudaju emi yoo si gbogbo won ni ona patapata '' Q39:82.
Ki a si tun lo mo pe wiwo inu esin Islam je ore nla ati oore pataki lati odo Olohun, o si je ifini se konge ti Olohun ma nse fun eni ti o ba fe ninu awon erusin re. Eni ti Olohun ba ri ododo erongba pelu adojuko daadaa ati irankan ododo lati mo oju ona ti o to ati lati rin oju ona naa, Olohun yoo se ni irorun fun ni gbogbo ona lati de ibe. Gbiyanju (ire ololufe mi) ki o je okan ninu awon ti yoo se konge lo sibi orire naa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"يَمُنُّونَ عَلَيْكَ أَنْ أَسْلَمُوا قُلْ لَا تَمُنُّوا عَلَيَّ إِسْلَامَكُمْ بَلِ اللَّهُ يَمُنُّ عَلَيْكُمْ أَنْ هَدَاكُمْ لِلْإِيمَانِ إِنْ كُنْتُم صَادِقِين "
'' won yoo ma se iregun fun o nitoripe won gba (esin) Islam. Sope: e ma wule se iregun fun mi lori gbigba (esin) Islam yin. Sugbon Olohun ni o le se iregun le yin loriww nitoripe O fi yin mona lo sibi igbagbo ododo, ti eyin ba je olododo '' Q49:17.

Dr. Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
[email protected]
www.islamland.com


DAJUDAJU ESIN KANSOSO TI NBE NI ODO OLOHUN NI ESIN ISLAM
 Dajudaju esin Islam ni esin eyi ti Olohun gbe gbogbo awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) dide le lori, bere latori Anabi Adamo (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Oun si ni esin ti Olohun yonu si fun gbogbo agbaye patapata, ti eniyan ni tabi alijonnu, titi ti Olohun yoo fi jogun ile ati awon oun ti o wa lori re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" إِنَّ الدِّينَ عِنْدَ اللَّهِ الْإِسْلَامُ "
'' dajudaju esin(kansoso) ti nbe lodo Olohun ni (esin) Islam '' Q3:19. O npepe lo sibi ise Olohun ni okan soso ati sise afomo ijosin fun Oun nikan soso lai lorogun. Eleyi ni ipepe gbogbo awon anabi ati awon ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won). Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
 "شَرَعَ لَكُمْ مِنَ الدِّينِ مَا وَصَّى بِهِ نُوحًا وَالَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ وَمَا وَصَّيْنَا بِهِ إِبْرَاهِيمَ وَمُوسَى وَعِيسَى أَنْ أَقِيمُوا الدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُوا فِيهِ..."
'' O se lofin fun yin nipa esin oun ti O pa lase fun Nuha ati eyiti A fi ranse si o ati eyiti A so asotele fun Ibrahim ati Musa ati Isa, pe ki e gbe esin duro atipe ki e mase pin yeleyele nidi re …'' Q42:13.
Awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) ti Olohun ran siwaju Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je awon eni ti Olohun ran si awon ijo won nikan soso fun asiko kan perete. Ti anabi kan ba ti papoda, ti ojo si ti lo lori re, ti awon eniyan si ti bere iyapa ilana re pelu mima se ebo ati pipa ilana re ti, ti abosi ati iyanje ti wa kari ile kari oko, igbanaa Olohun yoo gbe anabi miran dide lati ta won ji lori awon oun ti o ti bo fun won ninu ilana ati ofin ti o siwaju. Yoo si pe won lotun lo sibi ima josin fun Olohun nikan soso ati pipa ilana ebo ti, ati mima josin fun elomiran leyin Olohun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَسُولًا أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاجْتَنِبُوا الطَّاغُوتَ "
'' nipaapaa A ti gbe ojise kookan dide ninu ijo kookan (ti o nso fun won pe) e ma josin fun Olohun nikan soso, ki e si jinna si awon orisa '' Q16:36.
 Eniti o si je opin awon Anabi ati awon Ojise wonyi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) naa ni Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Olohun gbe dide leyin idaduro wiwa awon ojise ki o le je ikeyin fun awon Anabi ati awon Ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won), ki ilana ofin tire si le je opin awon ilana ofin, ki ipepe re si le wa fun gbogbo agbaye patapata, leni ti yoo ma se iro idunnu (fun awon eni rere) ti yoo si je olukilo (fun awon alaigbagbo nibi iya), yala fun awon eniyan tabi awon alijonu, alawo funfun ni won je ni tabi alawo dudu, larubawa ni won ni tabi awon ti ki se larubawa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا كَافَّةً لِلنَّاسِ بَشِيرًا وَنَذِيرًا "
'' Atipe Awa ko wule ran o nise ayafi si gbogbo eniyan patapata, (ki o le je) olu se iro idunnu (fun awon onigbagbo ododo) ati olukilo (iya fun awon alaigbagbo). Q34:28
Eleyi ni o si fa ti ilana ofin ise ti won fi ran Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se yato si ti awon ti o siwaju re, pelu awon orisirisi iroyin ati esa, eyi ti o je ki o ma se deedee pelu gbogbo idagbasoke awujo. O doju ipepe re ko gbogbo eniyan patapata lai fi ti iran tabi eya se. Ninu awon iroyin esa ti nbe fun ipepe naa ni pe o je ti gbogbo agbaye, ti o kun fun ike omoniyan (ni gbogbo agbegbe). Eleyi ni oun ti Olohun so ninu oro Re pe:
"وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ"
''Atipe Awa ko wule ran o nise ayafi ki o le je ike fun gbogbo agbaye '' Q21:107.
Bakan naa o je eyi ti o kun keke fun awon ofin ati ilana ti o nse amojuto awon eto igboke gbodo enikookan, akojopo awon eniyan ati ajosepo pelu awon awujo ti o rokirika re. Awon eleyi ni okunfa ilosiwaju ati ima be gbere ti Olohun se fun esin naa, ti o si je ki o ma je eyi ti nba gbogbo igba ati asiko patapata mu, titi ti Olohun yoo fi jogun ile ati awon oun ti o wa lori re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا "
'' Loni yi Mo ti se esin yin ni pipe fun yin, atipe Mo se asepe idera Mi leyin lori atipe mo yonu si Islam ni esin fun yin '' Q5:3.
Nigba ti o je wipe irorun, irora ati ede je oun pataki ti o ma nje ki emi nife ati lati gba adisokan (irori) wole, eleyi lo fa ti o fi jepe iroyin esa ti esin Islam duro le lori naa ni IRORUN eyi ti o foju han gbangba gbangba nibi rirorun awon ofin ati ilana ijosin re. Igbalaaye ati ise ede eyi ti awon ofin ati ilana ijosin yi ko sinu ni o je ki o rorun fun gbogbo eniyan lati lo awon ilana naa ati lati fi sise ni ibamu si ikapani ati agbara won ni gbogbo asiko ati aaye ti awon eniyan ti nsemi lori ile ni ibamu si ase Olohun ati Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba).
Ilana re naa ni eyi ti o wa ni ibamu si oro Olohun ti o sope:
"لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا "
'' Olohun ko gbe eru ti o ju enikan lo le lori bi ko se bi agbara re ti mo '' Q2:286.
Ati oro Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o sope:
"دَعُونِي ما تَرَكْتُكُمْ إنما أهلك من كان قَبْلَكُمْ سؤالهم وَاخْتِلَافِهِمْ على أَنْبِيَائِهِمْ فإذا نَهَيْتُكُمْ عن شَيْءٍ فَاجْتَنِبُوهُ وإذا أَمَرْتُكُمْ بِأَمْرٍ فَأْتُوا منه ما اسْتَطَعْتُمْ "
'' e ma yomi lenu lori oun ti mi o ba so fun yin, toripe oun ti o se okunfa iparun fun awon ti won siwaju yin ni ibeere won ti o poju ati ima ko oro si awon anabi won lenu. Ti mo ba ko nkankan fun yin, e kuro nibe patapata, ti mo ba si payin lase nkankan, e se bi e ba se lagbara (Al Bukhari).
Dajudaju irorun esin Islam je origun ipile ti awon ofin esin Islam duro le lori. Bere lati ori eyi ti o je oga gbogbo alamori, eyi ti se adisokan (igbagbo) titi ti o fi de ori eyi ti o kere julo ninu won. Ko si lori alaborun tabi inira, ko si ifunlemoni ti ma nso eto di eewo tabi atetere (ateewo) ti yoo so eewo di eto. Ko le ma ri be, nigba ti o jepe ilana ti a gbe kale fun omoniyan ni, ti aimoye adinku si ma nsele si won, bakan naa ni won si ni adamo, isesi ati ikapani orisirisi ti o yato si ara won. Gbogbo awon adamo ati isesi pelu ikapani oniranran wonyi ni ofin esin Islam se akiyesi re, nitoripe o je esin ti o se deedee adamo, ti o si wa ni ibamu si pelu. O faye sile fun enikookan lati se ijosin ni ibamu si ikapani re ati eyikeyi ipo ti o ba a wa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
 "وَمَا جَعَلَ عَلَيْكُمْ فِي الدِّينِ مِنْ حَرَجٍ "
'' Ko se isoro kankan fun yin ninu esin '' Q22:78.
 Eleyi lo fi jepe ilana ofin esin Islam je eyi ti o rorun, nitori ede irora ati imu inira kuro funni pelu dedena isoro fun omoniyan, eyi ti o wa nibe fun awon oluse esin naa, eleyi ni o si so di oun ti gbogbo awujo musulumi nife si pupo, bio tile jepe won ju ara won lo ni ipo ati irori sugbon enikookan won ni o ni adun nibi lilo ofin esin ati nibi fifi sise se.
 Awon ti won je onideedee ninu awon ti ki se musulumi naa jeri lori iroyin yi. Awon ofin esin Islam je eyi ti o jepe bi o se nse akolekan awon oloro naa lo nse akolekan awon alaini, bi o se nse akiyesi eni ti o ni alafia bee lo nse akiyesi alaisan, bi o se nse akolekan agbalagb gege ee naa lo nse akolekan omode, bi o se ni akolekan obinrin naa ni o ni akolekan okunrin, bi o se nse akolekan olori bee naa lo nse akolekan omoleyin, o se akiyesi aaye ati igba kookan. Omoniyan lati lailai wa ko mo ofin kan ti ipile re yoo duro lori ilana iwontun wonsi, irorun ati irora bayi gegebi ti esin Islam. Eleyi ti o nyumo si pe ofin esin Islam se deedee pelu adamo omoniyan, eyi ti Olohun ni eni ti o le. Olohun ti ola Re ga so bayi pe
"يرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُخَفِّفَ عَنْكُمْ وَخُلِقَ الْإِنْسَانُ ضَعِيفاً "
'' Olohun nfe lati se irorun fun yin, (toripe) A da omoniyan ni ole '' Q4:28.
Dajudaju irorun ati irora esin Islam eyi ti o duro lori mimu inira ati isoro kuro fun je eyi ti o ko musulumi ati eni ti ki se musuumi sinu. Igbe dide Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je orire fun awon elesin ti o siwaju esin Islam, toripe o je okunfa mimu awon inira ati ilekoko ti o wa ninu awon esin wonyi kuro, ti o si fi idera ropo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ الرَّسُولَ النَّبِيَّ الْأُمِّيَّ الَّذِي يَجِدُونَهُ مَكْتُوبًا عِنْدَهُمْ فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنْجِيلِ يَأْمُرُهُمْ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَاهُمْ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُحِلُّ لَهُمُ الطَّيِّبَاتِ وَيُحَرِّمُ عَلَيْهِمُ الْخَبَائِثَ وَيَضَعُ عَنْهُمْ إِصْرَهُمْ وَالْأَغْلَالَ الَّتِي كَانَتْ عَلَيْهِمْ فَالَّذِينَ آمَنُوا بِهِ وَعَزَّرُوهُ وَنَصَرُوهُ وَاتَّبَعُوا النُّورَ الَّذِي أُنْزِلَ مَعَهُ أُولَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ"
'' Awon naa ni eniti won ntele ti ojise naa, Anabi naa, eni ti ko mo o ko ti ko mo o ka, eniti won ba akosile nipa re lodo won ninu At Taorata ati ninu Al Injila, yoo ma pawon lase iwa rere, yoo si ma ko aburu fun won, yoo si ma se awon oun ti o dara ni eto fun won, yoo si ma se awon oun ti ko dara ni eewon fun won, yoo si ma gbe awon eru ti o wuwo kuro fun won ati ajaga ti nbe fun won, awon ti o ba gba a gbo ti won si bu owo fun un ti won si ran lowo ti won tele imole ti a so kale pelu re, awon eleyi ni won o jere '' Q7:157.
 Ninu ilana irorun yi naa ni fifi aye igbiyanju esin(Ijtihadu) sile (fun awon alufa) ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fi lele, nigba ti o ran Maa'dh omo Jabal lo si ile Yamoni ti o si bi leere wipe:
"بمَ تحكمُ ؟ قالَ: بِكِتابِ اللَّهِ. قالَ: فإن لم تجدْ ؟ قالَ: بسُنَّةِ رسولِ اللَّهِ. قالَ: فإن لم تجدْ ؟ قالَ: أجتَهِدُ برأيي. قالَ: فضربَ رسولُ اللَّهِ صلَّى اللَّهُ عليهِ وسلَّمَ في صدرِهِ، وقالَ: الحمدُ للَّهِ الَّذي وفَّقَ رسولَ رسولِ اللَّهِ لما يُرضي رسولُ اللَّهِ." صححه أحمد شاكر
'' kini o fi mo dajo? O dahun wipe: iwe Olohun (Al kurani), o tun beere wipe: ti o ba si nibe nko? o tun dahun wipe: ilana Ojise Olohun (as sunnah) (ike ati ola Olohun ki o ma ba), o tun beere wipe: ti ko si nibe nko? o si dahun wipe: ma se igbiyaju pelu irori (imo) mi. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa fowo gba laya o si sope: ope ni fun Olohun ti O fi ojise Ojise Olohun se konge lo sibi oun ti o yo Ojise Olohun ninu. (Ahmad Shakir sope egbewa ti o fese rinle ni).
Eleyi ni o si je ki o je esin ti o gba gbogbo idagbasoke wole, ti o si ba gbogbo igba ati gbogbo aye mu. Esin Islam duro lori awon ipile ati awon opo kan ti o duro sinsin ti ko le yi pada lailai, yala ni eyikeyi aaye tabi igba. Awon eleyi wa nibi abala adisokan ati ijosin, gegebi igbagbo (Al eeman) ati irun kiki (As salah): onka re, asiko re, bakan naa saka yiyo (Az zakah): osunwo re, awon oun ti o je oranyan ki a yo o nibe, ati awe gbigba (As sawm): asiko re, pelu ise haji sise (Al hajj): bawo ni a se se, asiko re, ati awon aala re, ati beebee lo. Awon oun ti o ba je isele igba ati awon nkan titun inu awujo a o dari re sinu Al kurani, eyi ti a ba ri (idajo re) nibe a o sise ni ibamu si oro Al kurani, eyi ti ko ba si nibe a o da pada sinu oro Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), ti a ba ri (idajo re) nibe a o sise ni ibamu si, eyi ti ko ba si nibe, o di ise igbiyanju awon aafa ti won jindo ninu imo esin ni asiko tabi aaye naa lati woye si i ni ibamu si oun ti yoo mu oore wa fun awujo.
 Sise igbayanju gbodo je eyi ti yoo se deedee pelu igba ati ipo ti awujo won wa, ati pelu iwoye si oro Olohun ati ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Pelu wiwon awon isele tuntun awujo won pelu awon opo tabi ipile ofin esin ti o kari, ti a fa jade lati inu Al kurani ati sunnah, fun apere: '' eto ni ipile gbogbo nkan '', ati '' didabobo awon oun anfani '', ati'' sise idera ati gbigbe ilekoko kuro '', ati'' imu inira kuro '', ati'' inira ma nso eewo di eto '', ati '' a ki gbe inira (kuro) ju bi o se wa lo '', ati '' (ipo) mimu inira kuro ga ju ki owo te anfani lo '', ati '' sise eyi ti aburu re kere julo ninu meji '', ati '' a ki mu inira kuro pelu inira '', ati '' fifaramo inira ti ara eni ki inira ti yoo kari ma le sele '' ati beebee lo ninu awon opo ofin esin wonyi.
Igbiyanju lori oro esin ti a nso ko si lori ife inu ati ima wa ona fun ojukokoro ati ifekufe emi. Eyi ti a nsoro re ni eyi ti yoo mu anfaniati oore wa fun omoniyan lai ni tako awon oro Olohun ati ti ojise Re. Won se agbekale oro igbiyanju esin yi ki o le jepe esin Islam yoo ma wa ni ibamu si gbogbo igba ati aaye ati ipenija igba kookan. Oro ti a nso yi ki se oro ori lasa, sugbon o je oun ti o wa ni ibamu si oro Olohun ati ti Ojise Re (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti n salaye nipa irorun ati idera esin Islam.


ILANA IRORUN NINU ESIN ISLAM
Oro nipa irorun ti o wa ninu esin Islam ki se oun ti a le yo soto ninu awon aketun esin Islam, biko sepe o je oro nipa odidi esin Islam lakotan. Eleyi ri be, nitoripe irorun yi wa ninu ikookan ninu awon aketun esin Islam. Bawo ni ko se ni ri bee? Nigba ti o je pe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti so pe:
" خير دينكم أيسره"
'' eyi ti o loore julo ninu esin yin naa ni eyi ti o rorun julo ninu re '' (Ahmad). O tun so ninu oro re miran wipe:
"أَحَبُّ الدِّينِ إلى اللَّهِ الْحَنِيفِيَّةُ السَّمْحَةُ"
'' eyi ti Olohun feran julo ninu esin ni eyi ti o duro deedee ti o si rorun '' (Al Bukhari).
Esin Islam je ilana irorun ti o pe perepere, o si je esin iwontun- wonsi (aarin meji), lori eleyi ni Olohun sope:
" وَكَذَلِكَ جَعَلْنَاكُمْ أُمَّةً وَسَطًا لِتَكُونُوا شُهَدَاءَ عَلَى النَّاسِ وَيَكُونَ الرَّسُولُ عَلَيْكُمْ شَهِيدًا "
'' Atipe gege be ni A se yin ni ijo aarin meji, ki e le ba je eleri lori awon eniyan, ki ojise naa si le je eleri leyin lori '' Q2:143.
Ninu awon apere idera ati irorun esin Islam ni awon agbegbe orisirisi:
1 - O je esin ti o mu irorun wa ni abala iselu ati ibasepo ilu si ilu, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"لَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُمْ مِنْ دِيَارِكُمْ أَنْ تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ (8) " الممتحنة 8
''Olohun ko ko fun yin nipa awon eni ti won ko gbogun tiyin lori esin, ti won ko si leyin jade kuro ninu ile yin, wipe ki e ma se daadaa si won ati ki e ma se deede pelu won, dajudaju Olohun feran awon oluse deede " Q60:8.
2 – O je esin ti o mu irorun wa ni abala eto awujo, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِنْدَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ (13) "الحجرات 13
'' Eyin eniyan A da yin lati ara okunrin kan ati obinrin kan, A si se yin ni orile-ede ati iran-iran ki e le ma da ara yin mo. Dajudaju eni ti o ni ola ju lodo Olohun ninu yin ni eni ti o paya (Re) julo ninu yin. Dajudaju Olohun ni Onimimo Olufun-ni-niro '' Q49:13.
3 – O je esin ti o mu irorun wa ni abala iwa, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" خُذِ الْعَفْوَ وَأْمُرْ بِالْعُرْفِ وَأَعْرِضْ عَنِ الْجَاهِلِينَ (199) " الأعراف
'' se amojukuro ki o si ma pase iwa rere, ki o si seri kuro lodo awon alaimokan '' Q7:199.
Olohun ti ola Re ga tun ninu oro Re bayi pe:
 " الَّذِينَ يُنْفِقُونَ فِي السَّرَّاءِ وَالضَّرَّاءِ وَالْكَاظِمِينَ الْغَيْظَ وَالْعَافِينَ عَنِ النَّاسِ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُحْسِنِين " آل عمران 134
''Awon ti won nna (dukia won) nigba idera ati nigba inira, ati awon ti won ma ngbe ibinu mi, ati awon olumojukuro (nibi asise) fun awon eniyan. Olohun feran awon oluse rere '' Q3:134.
Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:
" وَلَا تَسْتَوِي الْحَسَنَةُ وَلَا السَّيِّئَةُ ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ فَإِذَا الَّذِي بَيْنَكَ وَبَيْنَهُ عَدَاوَةٌ كَأَنَّهُ وَلِيٌّ حَمِيمٌ"
'' iwa rere ati iwa aburu ko le se deede ara won-on, ma fi iwa rere se adapada (iwa aburu), toripe eniti ota nbe laarin iwo pelu re le wa di ore imule '' Q41:34.
4 – O je esin ti o mu irorun wa ni abala ijosin, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَا نُكَلِّفُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا أُولَئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ (42) " الأعراف
'' Atipe awon onigbagbo ododo ti won nse ise rere, A ko la bo emi kankan lorun ayafi oun ti o lagbara, awon wonyi ni ero ogba idera (Al-jannah) won yoo si ma wa nibe lo gbere " Q7:42.
5 – O je esin ti o mu irorun wa ni abala eto isuna, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" الَّذِينَ يَأْكُلُونَ الرِّبَا لَا يَقُومُونَ إِلَّا كَمَا يَقُومُ الَّذِي يَتَخَبَّطُهُ الشَّيْطَانُ مِنَ الْمَسِّ ذَلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا إِنَّمَا الْبَيْعُ مِثْلُ الرِّبَا وَأَحَلَّ اللَّهُ الْبَيْعَ وَحَرَّمَ الرِّبَا فَمَنْ جَاءَهُ مَوْعِظَةٌ مِنْ رَبِّهِ فَانْتَهَى فَلَهُ مَا سَلَفَ وَأَمْرُهُ إِلَى اللَّهِ وَمَنْ عَادَ فَأُولَئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ" البقرة 275
" Awon ti won nje owo-ele, won ko ni dide (ni ojo idajo) ayafi gegebi idide eniti esu nla mole latara fifi owo (re) kan-an. Eleyi ri bee, nitoripe won sope; owo-sise (tita-rira) da gegebi owo-ele, Olohun se owo-sise ni eto O si se owo-ele ni eewo. Enikeni (nigba naa) ti ikilo ba de odo re lati odo Oluwa re ti o si jawo (ninu owo-ele) tire ni eyi ti o ti koja, oro re si nbe ni odo Olohun, sugbon eniti o ba tun pada (si idi owo-ele), awon wonyi ni ero ina, won yoo si ma wa nibe lo gbere " Q2:275.
6 – O je esin irorun ni abala ibara-eni-sepo, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَقُلْ لِعِبَادِي يَقُولُوا الَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِنَّ الشَّيْطَانَ يَنْزَغُ بَيْنَهُمْ إِنَّ الشَّيْطَانَ كَانَ لِلْإِنْسَانِ عَدُوًّا مُبِينًا " الإسراء 53
" So fun awon olujosin fun Mi pe ki won ma so eyi ti o dara julo (ninu oro). Dajudaju esu yoo ma da iyapa sile laarin won. Dajudaju esu je ota ti o fojuhan gbangba si omoniyan " Q17:53.
7 - O je esin irorun ni abala ireni ati ikoni ni eko, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" يسروا ولاتعسروا وبشروا ولا تنفروا " متفق عليه
" E ma se nkan pelu irorun, e ma mu nkan le koko, e ma fun (awon eniyan) ni iro idunnu, e ma ma deru ba won '' (Al Bukari ati Muslim).
 Orisirisi awon oro ti o wa nipa ofin esin ni o nse afirinle ilana idera ati irorun, latara mima se ni ni ojukokoro lilo awon ofin wonyi laarin awujo esin nibi isesi enikookan. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so ninu oro re pe:
" إن الرفق لا يكون في شيء إلا زانه ولا يُنزع من شيء إلا شانه ". رواه مسلم. وقال صلى الله عليه وسلم: « اسْمَحْ يُسْمَحْ لَكَ ».
" Dajudaju ise pelepele ko ni ma wa ninu nkan kan ayafi ki o se nkan naa loso, bakan naa ko ni kuro ninu nkan kan ayafi ki o ko abuku ba nkan naa'' (Muslim). Ati oro re ti o so pe " maa se idekun Olohun yoo se idekun fun iwo naa " (Ahmad).
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun so pe:
" إن الله يحب الرفق في الأمر كله " متفق عليه
'' Dajudaju Olohun feran sise pelepele nibi gbogbo nkan " (Al Bukari ati Muslim).
 Bakan naa esin Islam fe ki a ri ara wa gegebi ikankan-naa nigba ti a ba wa ni akojo. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se adua fun eni ti o ba nse pelepele pelu awon ijo re ti o si fi sise irorun ati idera se ilana ti o nlo nibi idari re. O so bayi ninu adua naa wipe
" اللهم من ولي من أمر أمتي شيئاً فشقَّ عليهم فاشقق عليه، ومن ولي من أمر أمتي شيئاً فرفق بهم، فارفق به ". رواه مسلم.
" ire olohun, eyikeyi ninu awon eniyan ti won ba yan fun awon ijo mi lori nkankan, ti o wa fi ara niwon (nibe), Olohun fi ara ni oun naa, bakan naa eniti won ba yan fun awon ijo mi lori nkankan ti o si se irorun pelu won, Olohun se irorun fun oun naa " (Muslim).
 Esin Islam gbe awon iseni-loju-kokoro ti o npeni lo sibi gbigba iroyin pelu sise irorun, o se e ninu awon okunfa wiwo ogba idera (Al jannah) ati gbigbe-ni jinna si ina. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
"من كان هينا لينا قريبا حرمه الله على النار " رواه الحاكم
" Eniti o ba je oniwapele ti o ko awon eniyan mora ti awon eniyan sinsumo, Olohun yoo se (wiwo) ina ni eewo re " (Al-haakim).
 Bakan naa, o ye ki o di mimo wipe irorun ati irora wonyi wa lori awon alamori ijosin ti ko si mu idojti ba awon erongba ati afojusun esin rara, ko si fun siso eewo di eto tabi siso eto di eewo, ko mu sise aseeto dani nibi idajo tabi imuse awon ase eyi ti esin pa, ko si si fun fifi aaye kan awon agboye esin tabi awon eko ajosepo.
O je irorun ati irora ti ko mu ilekoko tabi inira dani ti o si jinna si ese ati iyapa Olohun. Aisha (Olohun ki o yonu si) ti o je iyawo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
"مَا خُيِّرَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ بَيْنَ أَمْرَيْنِ إِلَّا اخْتَارَ أَيْسَرَهُمَا؛ مَا لَمْ يَكُنْ إِثْمًا، فَإِذَا كَانَ إِثْمًا كَانَ أَبْعَدَ النَّاسِ مِنْهُ، وَمَا انْتَقَمَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِنَفْسِهِ، إِلَّا أَنْ تُنتهك حُرْمَةُ اللَّهِ تَعَالَى، فَيَنْتَقِمُ لِلَّهِ عَزَّ وَجَلَّ بها". مُتَّفق عَلَيْهِ واللفظ للبخاري
'' won ko ni yonda fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pe ki o sesa laarin nkan meji ayafi ki o sesa eyi ti o rorun julo ninu mejeeji, niwonba igba ti ki i ba se ese, ti o ba si je ese ni, oun ni eni ti o ma jinna si nkan naa julo. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki i gba esan nitori ara re, ayafi nigba ti (awon eniyan) ba fa ogba Olohun ya, nigbayini yoo si gbarata nitori ti Olohun Oba abiyi '' (Al Bukari ati Muslim).
Won se ayafi (iyonda) nigba ti omoniyan ba wa ni ipo inira, eleyi ti o ni idaju tire loto, yato si igba ti o ba wa ni ipo idera.
DIE NINU AWON ABALA IRORUN ATI IRORA ESIN ISLAM

IRORUN ESIN ISLAM NI ABALA ADISOKAN (IGBAGBO)
 Dajudaju igbagbo (adisokan) je ipile eyi ti esin Islam da le lori. O je opomulero ti ko ni afiwe tabi afijo. O je oun ti o jepe ti ko ba ti si fun omoniyan ko si esin fun onitoun, eleyi lo si fa ti Olohun ti ola re ga fi so wipe:
 "إِنَّ اللَّهَ لَا يَغْفِرُ أَنْ يُشْرَكَ بِهِ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَلِكَ لِمَنْ يَشَاءُ "
'' Dajudaju Olohun ko ni se aforijin (ese) sise ebo pelu Re, (sugbon) O ma nse aforijin (ese) eyi ti o ba kere si eleyi (ebo) fun eni ti O ba fe '' Q4:116.
Ninu awon apere irorun ati irora esin Islam ni abala igbagbo (Adisokan):
1-Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa ni bi o se se ni oun ti o fojuhan kedere ti ko si si rujuruju tabi itannije kankan ninu re. O se ni oun ti o rorun lati gboye fun alaimokan ki a to so ti onimimo, bakan naa ni fun omode ki a to wa so agbalagba. O pase igbagbo ninu Olohun pelu mima josin fun Oun nikan soso laisi alagata laarin won. Gbogbo eniyan ni adisokan yi wa fun, leyi ti ko ni asepo pelu awon iko kan laarin awon yoku. Adisokan ki i se eyi ti o ma nso lakaye omoniyan di eyi ti ko ni aponle tabi ti yoo so di nkan yepere, leyi ti yoo wa so di eni ti yoo ma se ijosin fun okuta, igi tabi eranko.
 Ninu irorun ati irora adisokan yi naa ni o fa ti larubawa-oko ti o ngbe ninu aginju se ni agboye re, nigba ti won bi leere nipa bawo ni o se da Olohun mo, ti o si dahun wipe: '' igbe rakunmi la fi mo rakunmi, oripa ese la si fi mo pe eniyan koja, nje oru-ganjo ti o dudu kirikiri ati ile ti o kun fun awon oju-ona pelu oke (sanmo) ti o kun fun irawo orisirisi ko wa ma toka lori (mima-be) Oba alaanu Olufunni-niro bi?
2- Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa ni bi o se se ni oranyan fun gbogbo elesin islam lati ni igbagbo ninu gbogbo awon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) ti won siwaju pelu awon iwe ti won sokale fun won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
 "آمَنَ الرَّسُولُ بِمَا أُنْزِلَ إِلَيْهِ مِنْ رَبِّهِ وَالْمُؤْمِنُونَ كُلٌّ آمَنَ بِاللَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْ رُسُلِهِ وَقَالُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا غُفْرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ (285) "(البقرة)
'' Ojise Olohun ni igbagbo si oun ti o sokale fun un lati odo Oluwa re, bakan naa si ni awon onigbagbo ododo. Enikookan won ni o gba Olohun gbo ati awon Molaika Re, ati awon Tira (iwe) Re, ati awon Ojise Re; awa ko ya okan soto ninu awon Ojise Re. Won so bayi pe: awa gbo a si gba (fa). Aforijin Re ni a nwa Ire Oluwa wa, odo Re naa si ni ipadasi '' Q2:285.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa ni wipe ko se ni oranyan fun enikeni lati ni adisokan yi, tabi lati wonu esin Islam lai te e lorun, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ فَمَنْ يَكْفُرْ بِالطَّاغُوتِ وَيُؤْمِنْ بِاللَّهِ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَى لَا انْفِصَامَ لَهَا وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ (256) " (البقرة)
'' ko si ifi tipatipa muni ninu esin (Islam) dajudaju imona ti fojuhan yato si ona anu. Nitorinaa eni ti o ba ko esu (Taguuti) ti o si gba Olohun gbo, (onitohun) ti diro mo okun ti o yi ti ko le ja, Olohun ni Olugbo Onimimo '' Q2:256.
Eleyi ri bee nitoripe awon eniyan pin si orisirisi ni abala esin latara fife Olohun, ko wa leto fun enikan lati je awon eniyan nipa lati je elesin Islam. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ لَآمَنَ مَنْ فِي الْأَرْضِ كُلُّهُمْ جَمِيعًا أَفَأَنْتَ تُكْرِهُ النَّاسَ حَتَّى يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ (99) " يونس 99
'' ti Oluwa re ba fe ni, gbogbo eni ti nbe lori ile ni ko ba gbagbo (ninu Olohun) patapata, nje iwo wa le mu awon eniyan ni tipatipa bi lati je onigbagbo ododo?'' Q11:99.
Enikeni ti ipepe esin Islam ba de etigbo re, ti ododo esin naa si fojuhan si, o leto fun onitohun lati sesa nini igbagbo ninu esin Islam, ni ibamu si ominira re lati gba tabi ko oun ti o de wa ba. Olohun ti ola Re ga so ni ibamu si eleyi pe:
"وَقُلِ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكُمْ فَمَنْ شَاءَ فَلْيُؤْمِنْ وَمَنْ شَاءَ فَلْيَكْفُرْ إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلظَّالِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمْ سُرَادِقُهَا وَإِنْ يَسْتَغِيثُوا يُغَاثُوا بِمَاءٍ كَالْمُهْلِ يَشْوِي الْوُجُوهَ بِئْسَ الشَّرَابُ وَسَاءَتْ مُرْتَفَقًا (29) "
'' So wipe: ododo lati odo Oluwa yin, eniti o ba fe ki o gbagbo eni ti o ba si fe ki o se aigbagbo. Dajudaju Awa ti pese ina fun awon alabosi, eyi ti ogba re yoo rokirika won. Ti won ba nwa iranlowo won yoo ran won lowo pelu omi ti o da bi ide, ti yoo si ma se awon oju won, o buru ni mimu, (inu ina) si buru ni aaye irogboku '' Q18:29.
4- Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa ni wipe sise idajo lori omoniyan duro lori oun ti o ba fojuhan ninu ise ati oro re lai ma se ofintoto lori aniyan re. Ofin ki i fi iyajeni lori oun ti nbe ninu emi (aniyan), toripe o je oun ti o pamo si aarin omoniyan ati Oluwa re ti enikankan ko si ikapani lati mo o.
5- Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa tun ni wipe nigbati ile ba fun mo omoniyan (ti won ba je e nipa) ko si laifi nibi ki o so oun ti o tako igbagbo re latari ifiyajeni naa ki o si le bo ninu inira ti o wa naa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"مَنْ كَفَرَ بِاللَّهِ مِنْ بَعْدِ إِيمَانِهِ إِلَّا مَنْ أُكْرِهَ وَقَلْبُهُ مُطْمَئِنٌّ بِالْإِيمَانِ وَلَكِنْ مَنْ شَرَحَ بِالْكُفْرِ صَدْرًا فَعَلَيْهِمْ غَضَبٌ مِنَ اللَّهِ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ (106) " النحل 106
'' Enikeni ti o ba se aigbagbo si Olohun leyin igbagbo re (ibinu Olohun nbe lori re), ayafi eniti won ba je nipa ti okan re si kun fun igbagbo, sugbon eniti o ba si igbaya re sile fun aigbagbo ibinu lati odo Olohun nbe lori won, bakan naa ti won ni iya ti o le koko '' Q16:106.
Eleyi je idaabobo fun musulumi lati ma ko si inu iya eleta-elero. Ninu awon apejuwe iru isele yi ni eyi ti o sele si
 عمار بن ياسر رضي الله عنه أخذه المشركون فلم يتركوه حتى سب(شتم) النبي صلى الله عليه وسلم وذكر آلهتهم بخير ثم تركوه فلما أتى رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:" ما وراءك؟" قال: شر يا رسول الله! ما تركت حتى نلت منك وذكرت آلهتهم بخير، قال:" كيف تجد قلبك؟" قال: مطمئن بالإيمان، قال:" إن عادوا فعد"رواه الحاكم
 A'maar omo Yaasir (Olohun ki o yonu si) ti o ko si owo awon alaigbagbo, ti won si fi tipatipa mu titi ti o fi bu Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o sin yin awon orisa won, leyin naa ni won fi sile, nigbati o de odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) o bi leere wipe; ki lo sele? O dahun wipe: aburu ni! won o fi mi sile titi ti mo fi so isokuso nipa re ti mo si se eyin fun awon orisa won, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe: bawo ni okan re se ri? O si dahun wipe: o kun fun igbagbo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si so fun wipe: ti won ba tun mu o leekan si tun se bi o ti se '' (Al Hakim).
 Bakan naa ni o sele si Bilal omo Rabah. Abdullah omo Masuu'd sope: awon eniyan meje ni won koko se afihan Islam won ninu awon musulumi; Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), Abu Bakri, Ammaar, ati iya re ti se sumayyah, Suhayb pelu Bilal ati Miqdaad. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ri idaabobo Olohun lati odo egbon baba re ti se Abu Talib, nigbati Abu Bakri si ri idabobo Olohun lati odo awon molebi re, sugbon awon yoku ko si owo awon osebo ti won si fi fila onirin bowon ni ori ti won si gbe won si inu oorun. Gbogbo awon yoku ni won se oun ti awon eniyan yi nfe ayafi Bilal toripe o ri emi re ni oun ti o yepere ni afiwe si titobi Olohun, bayi ni awon osebo yi si yepere oun naa, won si fa a le awon omode lowo, won si bere si ni wo kaakiri awon ojuona ilu Makkah ni eni ti si nso wipe: okansoso okansoso (ni Olohun). (Saheeh as seeratu An nabawiyah).
6- Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa tun ni bi o se la emi omoniyan kuro nibi mima josin fun nkan miran leyin Olohun yala anabi kan ti a ran nise ni tabi Malaika kan ti o je alasunmo. Eleyi ri bee latara igbagbo ododo ti o joko sinu igbaya musulumi wipe a ko gbodo beru enikankan ayafi Olohun, atipe ko si eni ti o le se ni anfaani tabi fi inira kan ni ayafi Olohun. Ko si enikankan ti o ni agbara botiwukomo lati se ni ni anfaani tabi fi inira kan ni tabi lati se daadaa fun ni tabi lati ko o fun niayafi pelu agbara ati iyonda Olohun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَاتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ آلِهَةً لَا يَخْلُقُونَ شَيْئًا وَهُمْ يُخْلَقُونَ وَلَا يَمْلِكُونَ لِأَنْفُسِهِمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا وَلَا يَمْلِكُونَ مَوْتًا وَلَا حَيَاةً وَلَا نُشُورًا (3) "
'' (Awon alaigbagbo) mu awon oluwa miran (ni oluwa won) leyin Re, ti won ko si le da nkankan, ti o si jepe won da awon naa ni, atipe won ko ni ikapani inira kan tabi anfaani kan fun ara won, won ko si ni ikapani iku tabi aaye ati igbende '' Q25:3.
Gbogbo alamori patapata wa lowo Olohun Oba olola. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَإِنْ يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ وَإِنْ يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلَا رَادَّ لِفَضْلِهِ يُصِيبُ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ (107) "
'' Ti Olohun ba mu inira kan ba o ko si eni ti o le mu u kuro ayafi Oun naa. Bi o ba si fe oore kan fun o ko si eni ti o le da oore Re pada, O ma nfi oun ti o ba fe kan eniti O ba fe ninu erusin Re, Oun si ni Oludarijin Alanu '' Q10:107.
Nitori ki esin Islam le dena ki omoniyan ma ni asopo emi pelu awon eniyan (nibi gbigbo bukata won) ati sise afomo won (niti ikojaala), ni o se salaye wipe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), pelu bi ipo re se ga to, ti ko si ni akegbe lodo Olohun, abara bi awon eniyan yoku ni oun naa, ofin ti o si de awon yoku naa ni o de oun naa. Ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba ri bayi bawo ni ti eni ti o yato si ninu eniyan yoo se wa ri? Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قُلْ لَا أَمْلِكُ لِنَفْسِي نَفْعًا وَلَا ضَرًّا إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ وَلَوْ كُنْتُ أَعْلَمُ الْغَيْبَ لَاسْتَكْثَرْتُ مِنَ الْخَيْرِ وَمَا مَسَّنِيَ السُّوءُ إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ (188) "
'' So wipe; emi ko ni ikapani anfaani kan fun ara mi bakan naa nko ni ikapani inira kan ayafi oun ti Olohun ba fe, ti o ba se pe mo mo oun ti o pamo nba wa opolopo oore fun ra mi aburu ko ba si ti sele simi, emi ko je nkankan ju olukilo ati olufunni ni iro idunnu lo fun awon ti won ni igbagbo ododo '' Q7:188.
7- Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa tun ni ki musulumi ni adisokan wipe Olohun pase deede laarin gbogbo eniyan patapata, lai fi ti esin, awo, iran tabi ipo se. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغْيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ (90) "
'' Dajudaju Olohun npase deede, daadaa (sise) ati fifun alasunmo (ni eto won), O si nko iwa ibaje, oun ti okan ko ati tenbelekun, O nse isiti fun ki e le ba gba iranti '' Q16:90.
Sise dedee pelu onile ati alejo je oun ti esin pepe si, ni ibamu si oro Olohun ti ola Re ga ti o sope:
:" وَإِذَا قُلْتُمْ فَاعْدِلُوا وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَى وَبِعَهْدِ اللَّهِ أَوْفُوا ذَلِكُمْ وَصَّاكُمْ بِهِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ (152) "
'' Bi e ba nsoro e se deedee koda ki o ba alasunmo (molebi) yi wi, ki e si ma pe adehun Olohun, eyi ni ase ti O pa yin ki e ba le gba isiti '' Q6:152.
Sise deedee nigba ti a ba nyonu tabi nigba ti a ba nbinu yala pelu eni ti o je musulumi tabi eni ti kii se musulumi je oun ti esin Islam se ni ilana, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ عَلَى أَلَّا تَعْدِلُوا اعْدِلُوا هُوَ أَقْرَبُ لِلتَّقْوَى (8) "
'' E ma je ki ikorira awon ijo kan koyin dese lori pe e ko ni se deedee, e se deedee oun ni o sunmo iberu (Olohun) '' Q5:8.
8- Ninu irorun esin Islam ni abala adisokan naa tun ni adisokan musulumi wipe Olohun se aponle omoniyan lapapo lori gbogbo oun ti Olohun da patapata, pelu bi esin won, awo won, iran won, ati ipo won se yato si ara won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلًا (70) "
'' Atipe dajudaju A ti se aponle fun awon omo Adamo, A mu won rin ni ori ile ati ni ori omi, A se ije-imu fun won latara awon oun ti o dara, A si gbe ola fun won lori opolopo awon nkan ti A se eda re ni ti ola nla '' Q17:70.
Jabir omo Abdullah (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) sope:
" مرت بِنَا جَنَازَةٌ فَقَامَ لها النبي صلى الله عليه وسلم وَقُمْنَا له فَقُلْنَا يا رَسُولَ اللَّهِ: إِنَّهَا جِنَازَةُ يَهُودِيٍّ ؟ قال:" إذا رَأَيْتُمْ الْجِنَازَةَ فَقُومُوا" البخاري ومسلم
'' Won gbe oku kan koja lara wa, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dide fun un, awa naa ba dide, a wa so pe ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba); oku elesin Yehuudi ma ni? O wa dahun wipe: ti e ba ri oku (ti won gbe koja) e ya dide fun '' (Al Bukari ati Muslim).
Sise ofin ati fifi ilana lile je oju-opo ti omoniyan ma nri lati se aseyori lori afojusun re tabi lati je ki erogba re te lowo. Ki omoniyan le ni aseyori lori erongba re, o gbodo ni oju-opo ti o yanju ti o si ni onde ti o si rorun ni ibamu si ikapani omoniyan, eyi ti yoo ma rin lori re.

DIE NINU AWON OJU-OPO IRORUN NI ABALA SISE OFIN ATI FIFI ILANA LELE NINU ESIN ISLAM
 1- Ninu irorun esin Islam ni abala ofin sise ni wipe awon oro Olohun ati ti Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti wa lori re je eyi ti o rorun pupo, Olohun ti ola re ga so bayi pe:
" وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِنْ مُدَّكِرٍ (17) "
'' Dajudaju A ti se Al-Kurani ni irorun fun iranti (Olohun). Nje oluranti nbe bi '' Q54:17.
Awon oro re fojuhan ko si si iruju tabi itakoko kankan nibe bi o ti wu ki o mo, ninu eto enikookan naa ni lati se ibeere nipa oun ti ko ba ye nibe tabi oun ti o nda lakaye laamu. Bi o tile jepe idahun lori awon ibeere nipa esin kii se eto gbogbo eniyan biko sepe ojuse awon onimimo ati awon ti o keko yanju nipa oro esin ti won si ni imo ati agboye nipa ijinle ati awon afojusun ati erongba idajo esin Islam. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"فَاسْأَلُوا أَهْلَ الذِّكْرِ إِنْ كُنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ (43) "
'' Nitorinaa e bi awon oniranti (onimimo) leere bi eyin ko ba mo ''Q16:43.
Bi o ti ri gele leyi, nitoripe eniti o ba nse aisan, fun apere, ki yoo gba odo onimo ero tabi onimo ogbin lo dipo dokita lo. Esin Islam ka ima soro nipa idajo esin lai ni imo ti o jindo nipa re si okan ninu awon iya ese. Nitoripe enikeni ti o ba soro nipa idajo esin laini imo ti o to le fi aimokan re so eto di eewo tabi ki o so eewo di eto, tabi ki o si ra eto elomiran lare, ti yoo si wa ko ara re tabi elomiran sinu iyonu abi inira. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قُلْ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَالْإِثْمَ وَالْبَغْيَ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَأَنْ تُشْرِكُوا بِاللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا وَأَنْ تَقُولُوا عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ (33) "
'' So wipe; awon nkan ti Oluwa mi se ni eewo ni iwa ibaje eyi ti o fojuhan ninu won ati eyi ti o pamo, ati ese ati tenbelekun lai leto, ati ki e tun ma ba Olohun wa orogun (ebo sise) eyiti (Olohun) ko so eri kankan kale le lori, atipe ki e si tun ma so oun ti e ko mo nipa Olohun '' Q7:33.
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni paapaa ti salaye awon oun ti yoo je abajade ima beere idajo oro esin lowo awon ti kii se onimimo idajo esin, o so bayi pe:
" إن الله لا يقبض العلم انتزاعا ينتزعه من العباد ولكن يقبض العلم بقبض العلماء حتى إذا لم يبق عالما اتخذ الناس رؤوسا جهالا فسئلوا فأفتوا بغير علم فضلوا وأضلوا "متفقٌ عَلَيْهِ.
'' Dajudaju Olohun ko ni ko imo kuro nile pelu fifayo kuro lara awon olujosin ni tipatipa, sugbon yoo ko kuro nile pelu kiku awon onimimo, ti o fi jepe nigba ti ko ba si onimimo kankan mo, awon eniyan yoo so awon alaimokan di asiwaju, won yoo si ma bi won (nipa idajo esin), won yoo si ma dajo (oro esin) pelu aimokan, bayi ni won yoo sina (sonu) ti won yoo si tun si awon eniyan lona '' (Al Bukhari ati Muslim).
Ko si awon idajo (oro esin) ti o sokunkun ninu esin Islam, leyi ti ko ye ki a beere nipa re siwaju ki a to ni igbagbo si, ayafi awon nkan ti o koja lakaye (oye) omoniyan ti opolo won ko si le lepa ba ninu awon alamori ti o pamo ti Olohun ti ola Re ga ko salaye lori re. Awon eleyi si ri bee nitoripe mimo re ko ni anfaani ti yoo se fun omoniyan, bakan naa lakaye won ni adamo bi Olohun se daa ko ni ikapani lati gbo paapaa adamo awon nkan wonyi ye. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
 "وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الرُّوحِ قُلِ الرُّوحُ مِنْ أَمْرِ رَبِّي وَمَا أوتِيتُمْ مِنَ الْعِلْمِ إِلَّا قَلِيلًا (85) ".
'' Atipe won yoo bi o leere nipa emi, so wipe; Emi nbe ninu ase Oluwa mi, atipe A ko fun yin ninu imo ayafi die '' Q17:85.
Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:
" يَسْأَلُونَكَ عَنِ السَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَاهَا (42) فِيمَ أَنْتَ مِنْ ذِكْرَاهَا (43) إِلَى رَبِّكَ مُنْتَهَاهَا (44) إِنَّمَا أَنْتَ مُنْذِرُ مَنْ يَخْشَاهَا (45) كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَاهَا (46) "
'' Won yoo bi o leere nipa akoko pe igba wo ni yoo to (42) \\ Ko si imo re ni odo re (ire Ojise, ona wo ni iwo fi le wa ranti tabi se iwadi re)? (43) \\ Odo Oluwa re ni opin (mimo) re wa (44) \\ Ire si je olukilo fun eniti nberu re (ojo ajinde) (45) \\ yoo si jo loju won lojo ti won ba ri i (ajinde) gegebi enipe won ko lo ju asale kan tabi owuro kan lo (46) '' Q79:42-46.
 Sugbon awon nkan ti anfaani nbe fun omoniyan nibi mimo re ninu awon oun ti o pamo Olohun ti ola Re ga ti salaye re lati ori ahon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), gegebi Al-Jannah (ogba idera), Ina, Isiro-ise, oro nipa awon ijo ti o ti siwaju pelu awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) won, fun iwoye, isiti ati iranti pelu imura sile (fun ojo ajinde) pelu ise rere. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"فَأَنْذَرْتُكُمْ نَارًا تَلَظَّى (14) لَا يَصْلَاهَا إِلَّا الْأَشْقَى (15) الَّذِي كَذَّبَ وَتَوَلَّى (16) وَسَيُجَنَّبُهَا الْأَتْقَى (17) الَّذِي يُؤْتِي مَالَهُ يَتَزَكَّى (18) وَمَا لِأَحَدٍ عِنْدَهُ مِنْ نِعْمَةٍ تُجْزَى (19) إِلَّا ابْتِغَاءَ وَجْهِ رَبِّهِ الْأَعْلَى (20) وَلَسَوْفَ يَرْضَى (21) "
'' Nitorinaa Emi fi ina ti on jo fofo se ikilo fun yin (14) \\ Ti enikankan ko ni wo o ju olori buruku lo (15) \\ eni ti o pe (otito) niro ti o si gunri (16) \\ Atipe awon olupaya (Olohun) A ogbe won jinna si (17) \\ eniti o fi owo re tore, lati se afomo emi re (18) \\ Atipe ko si enikan ti o ni oore idera kan lodo re lati fi gba esan (19) \\ Ayafi lati fi wa ojure Oluwa re ti o ga julo (20) \\ Atipe laipe yoo di eniti nyonu '' Q93:14-21.
2- Ninu irorun esin Islam ni abala ofin sise naa tun ni wipe awon oro lori re wa lati odo Olohun ti O da eda. Olohun ti O mo kanga yi ni O gbe e kale, Eni ti o je pe deedee ni gbogbo eda lodo Re, yala olori ni tabi omoleyin, olola ni tabi alaini, abiyi ni tabi eniyepere, eniyan dudu ni tabi eniyan funfun. Ko leto fun enikankan lati yapa re bi o ti wu ki ola tabi ipo re ga to. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ وَلَا مُؤْمِنَةٍ إِذَا قَضَى اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَمْرًا أَنْ يَكُونَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ مِنْ أَمْرِهِمْ وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَالًا مُبِينًا (36) "
'' Atipe ko leto fun onigbagbo ododo ni okunrin kan tabi obinrin pe nigba ti Olohun ati Ojise Re bati pari oro kan, wipe ki awon naa tun ma se esa oro miran funra won. Atipe eniti o ba yapa Olohun ati Ojise Re, o ti sina ni isina ti o foju han gbangba '' Q33:36.
 Eyi ti o je oranyan lori onikaluku ni ki o dunni mo awon ofin wonyi ki o si ma se aponle ati ifi sise won yala olori ni o je ni tabi omoleyin, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" إِنَّمَا كَانَ قَوْلَ الْمُؤْمِنِينَ إِذَا دُعُوا إِلَى اللَّهِ وَرَسُولِهِ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ أَنْ يَقُولُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا وَأُولَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ (51) "
'' Iba oun ti oro awon onigbagbo ododo yoo je, nigba ti A ba pe won si odo Olohun ati Ojise Re lati dajo laarin won, won yoo so pe; awa gbo awa si tele (e), atipe awon wonyi ni won yoo jere ''Q24:51.
 Ninu esin Islam ko si eniti o ga ju ofin lo ninu omoniyan, koda ki o je olori, gbogbo ola ati agbara ti n be fun olori nbe ni ibamu si oun ti ofin esin ba gbe kale. Eleyi je okan ninu awon irorun esin Islam ni abala ofin sise, ko gbodo si ijeninpa, ifipamuni tabi ijegaba ati ikojaala, ti olori ba wa se awon nkan wonyi ko leto lati tele ase re nibi awon iyapa Olohun naa, nitori oro Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o so pe:
" على المرء المسلم السمع والطاعة فيما أحب وكره إلا أن يؤمر بمعصية فإذا أمر بمعصية فلا سمع ولا طاعة "
'' O je dandan ki omoniyan ti o je musulumi ma gbo (ase olori) ki o si ma tele, lori oun ti o ni ife si ni tabi oun ti o korira, ayafi ti won ba pa lase iyapa Olohun, ti won ba wa pa lase iyapa Olohun ko gbodo gbo (ase naa) ko si gbodo tele e ''
Esin Islam lo ilana yi lati fi so awon eto ati ominira omoniyan ni okookan ni tabi ni apapo. Ilana sise ofin ninu esin Islam jinna si ifeenu olusofin ti o kuru, nitoripe iru ofin sise bayi ma nduro lori ifeenu awon ti ba ndari ilu. Sugbon awon isesi kookan ti ilana ofin sise ninu Islam ko soro nipa re wa fun ki awon mususlumi se agbekale awon eto ati ofin ti yoo ba awujo won mu ti yoo si mu anfaani gbogbogbo wa fun won, ni ibamu si igba ati aaye ti won wa. Bakan naa awon eto ati ilana yi gbodo je eyi ti ko ni tako awon ipile esin Islam ati awon ipile ofin sise.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala ofin sise naa tun ni wipe awon ofin wonyi ati awon eko re je eyi ti o wa lati odo Olohun leyi ti o fese rinle ti ko si fun iyipada tabi pasiparo. Kii se igbekale omoniyan eyi ti o kun fun aaye ati asise pelu ilapa awon orisirisi oun ti o rokirika re gegebi asa, isesi ajogunba ati awujo. Eniti o gbe ilana yi kale ni Adeda gbogbo eda patapata, Onimimo ati Alamodaju nipa oun ti o se deedee won, ti O si nse amojuto awon oro won. Ko leto fun enikeni ninu omoniyan, bi o ti wu ki ipo re ga to, ki o tako awon ofin wonyi tabi ki o paaro nkankan ninu oun ti Olohun se lofin yala pelu yiyo kuro ni tabi ki o se afikun re. Nitoripe eyi ti Olohun gbe kale yi ni o je ilana ti nso iwo gbogbo omoniyan ti o si wa lori ilana irorun ati irora. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" أَفَحُكْمَ الْجَاهِلِيَّةِ يَبْغُونَ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ حُكْمًا لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ (50) "
'' Idajo igba aimokan ni won ha nwa bi? Tani eni ti o dara ju Olohun lo ni idajo fun awon eniyan ti o mo amodaju (nipa re) '' Q5:50.
4- Ninu irorun esin Islam ni abala sise ofin naa tun ni pe, esin Islam ko ya agbara emi soto fun awon asiwaju esin nikan gege bi o se wa ninu awon esin ti o yato si esin Islam. Nitoripe esin Islam wa lati se apare gbogbo alagata laarin Olohun ati awon erusin Re. Eleyi ni o si fa ti o fi bu enu ate lu isesi awon osebo nibi mimu enikan ni alagata laarin awon ati Olohun nibi ijosin, Olohun ti ola Re ga so nipa won bayi pe:
" أَلَا لِلَّهِ الدِّينُ الْخَالِصُ وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللَّهِ زُلْفَى "
'' E teti yin ki e gbo, ti Olohun nikan ni esin ti o mo. Atipe awon eniti won mu ni alafayinti leyin Olohun, (won yoo ma sope): Awa ko sin won bikose pe ki won le sun wa mo Olohun ni pekipeki '' Q39:3.
Olohun Oba mimo ti ola Re ga se alaye paapaa alagata wipe ko le seni ni anfaani ko si le ko inira bani, ko le ro won loro nkankan, atipe eda bi ti won naa ni oun naa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ عِبَادٌ أَمْثَالُكُمْ فَادْعُوهُمْ فَلْيَسْتَجِيبُوا لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ (194) "
'' Dajudaju awon eniti e npe leyin Olohun je eru bi tiyin naa; nje e pe won, ki awon si dayin lohun ti e ba je olododo '' Q7:194.
 Esin Islam se afirinle irori asopo laarin erusin ati Olohun lai ni alagata ninu eleyi ti o si duro lori igbagbo ododo ati isadi Olohun nikan nibi gbigbo bukata eni ati nibi wiwa ni alaforijin pelu titoro iranlowo lodo Re lai ni alagata ninu. Eniti o ba da ese fun apere ko si nkankan ti yoo se ju ki o gbe owo re soke ki o direbe lo sodo Olohun nikan soso ki o si toro aforijin lodo Re ni eyikeyi aaye, asiko tabi yowu ki o wa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَمَنْ يَعْمَلْ سُوءًا أَوْ يَظْلِمْ نَفْسَهُ ثُمَّ يَسْتَغْفِرِ اللَّهَ يَجِدِ اللَّهَ غَفُورًا رَحِيمًا (110) "
'' Enikeni ti o ba se ise aburu tabi se abosi emi ara re, leyin naa ti o wa wa Olohun ni alaforijin, yoo ri Olohun ni Alaforijin Alanu '' Q4:110.
Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:
" وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ " (غافر:60)
'' Atipe Oluwa yin sope; e pe mi ma dayin lohun '' Q40:60.
 Ko si ninu esin Islam awon eniyan kan ti won wa ni ipo agbara ninu esin, ti won le se oun ti o ba wu won leto tabi se oun ti o ba wu won ni eewo, ti won le se aforijin fun eniti won ba fe, ti won si ri ara won gegebi eniti o wa ni ipo asoju Olohun lori awon erusin Re, ti won yoo ma se eyi ti o ba wu won ninu ofin ti won yoo si ma dari adisokan si ona ti o ba wu won, won yoo ma se aforijin fun eniti o wu won, ti won yoo si ma fi eniti o ba wu won sinu ogba idera tabi yo eniti o ba wu won kuro nibe. Sise ofin ninu esin Islam je iwo Olohun nikan soso.
 Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so nigba ti o nsalaye itumo oro Olohun ti o so bayi pe:
" اتَّخَذُوا أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَابًا مِنْ دُونِ الله "
'' Won mu awon olujosin won ati awon alufa won ni oluwa miran leyin Olohun " Q9:31.; wipe:
" أما إنهم لم يكونوا يعبدونهم ولكنهم كانوا إذا أحلوا لهم شيئا استحلوه وإذا حرموا عليهم شيئا حرموه " صحيح سنن الترمذي
'' kii se pe won nse ijosin fun won, sugbon ti won ba se nkankan leto fun won, won yoo mu ni eto, ti won ba si se nkankan ni eewo fun won won yoo mu ni eewo '' (At-tirmidhi).
5- Ninu irorun esin Islam ni abala ofin sise naa tun ni eto (ijoko) idamoran. Eleyi wa fun lati je ki apero wa laarin awon ara awujo lori awon oro ti o ba ni se pelu anfaani gbogbogbo, ti yoo je ki iru awon alamori wonyi jinna si ijegaba awon eniyan perete lori awon eniyan toku. Awon agbala a si ma sope: otun woo osi woo, oun a ba jo wo gigun nii gun, atipe ogbon enikan ko jo ti opo eniyan. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
:" فَبِمَا رَحْمَةٍ مِنَ اللَّهِ لِنْتَ لَهُمْ وَلَوْ كُنْتَ فَظًّا غَلِيظَ الْقَلْبِ لَانْفَضُّوا مِنْ حَوْلِكَ فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاسْتَغْفِرْ لَهُمْ وَشَاوِرْهُمْ فِي الْأَمْرِ "
'' Nitori aanu ati odo Olohun wa, ni iwo fi ro fun won, iba sepe o je oniwa buburu (ati) olokan-lile ni won ko ba ti tuka kuro ni odo re, nitorinaa moju kuro fun won, ki o si toro aforijin fun won, ki o si ma ba won jiroro nipa alamori naa '' Q3:159.
6- Ninu irorun esin Islam ni abala sise ofin naa tun ni pe o fi aaye igbiyanju esin lele fun awon ti o danto ti won si yege ninu imo esin, lori awon alamori ti oro Olohun ati Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba) Re ko salaye lori re ninu Al-Kuran ati Sunnah.Eleyi nse afihan wipe esin Islam je esin ti o fi aaye sile fun ilosiwaju ati idagbasoke awujo ti o si ba gbogbo aaye tabi asiko mu.
 Esin Islam wa pelu awon eko ipile olowoye-biye ati awon ilana gbogbogbo, pelu awon opo ti o fese rinle ti ayipada ko le ba nigba kankan ni eyi keyi aye tabi asiko, yala ninu oro adisokan ni tabi oro ijosin, gegebi oro igbagbo tabi irun kiki; iye onka raka re, asiko re, tabi Zakat; odiwon re, awon nkan ti zakat wo, tabi aawe gbigba ati asiko re, hajji sise; bawo ni sise re, asiko re ati awon enu aala re ati beebee lo.
 Awon nkan ti o ba je nkan tuntun tabi isele igba yoo je oun ti a koko maa wa idajo re lo si inu Al-Kuran, eyi ti o ba wa nibe ao lo idajo naa, eyi ti a ko ba si ri nibe ao wa ninu awon eyi ti o fese rinle ninu awon oro Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), eyi ti o ba wa nibe ao lo idajo re. Sugbon ni igba ti a ko ba wa ri idajo re ni ona mejeeji ni ise wa di ise awon onimimo ti won je oluberu Olohun ni aaye ati asiko kookan lati woye si oro naa, ni ibamu si oun ti yoo je anfaani gbogbogbo ti yoo si wa ni ibamu si asiko ati isesi awujo won. Iwoye awon onimimo wonyi naa si gbodo wa ni ibamu si Al-Kurani ati Sunnah, ti won yoo si fi awon opo ati ipile ofin sise ti a mu lati inu Al-Kuran ati Sunnah se atona re ki iforigbari ma ba wa laarin awon mejeeji.
 Iwoye tabi igbiyanju lori oro esin yi ko si lori ifeenu tabi ifekufe emi. Idi pataki fun iwoye ati igbiyanju esin naa ni lati se amujade awon oun ti yoo je anfaani funomoniyan lai si ni tako oro Olohun tabi Ojise Re. Bakan naa si tun ni lati je ki esin Islam je oun ti yoo ma ba gbogbo igba ati asiko mu.
7- Ninu irorun esin Islam ni abala sise ofin naa tun ni lati dena aseju ati lilekoko ninu esin. Olohun ti ola Re ga ko ilekoko nine sin pelu oro Re ti o so bayi pe:
 "يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ "
'' Olohun nfe irorun pelu yin, ko si fe inira fun yin '' Q2:185.
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) naa so pe
 "إياكم والغلو في الدين، فإنما هلك من قبلكم بالغلو في الدين ". رواه الإمام أحمد والنسائي وصححه الألباني.
'' E sora fun aseju ninu esin, nitoripe oun ti o se okunfa iparun awon ti o siwaju yin naa ni aseju ninu esin '' (Ahmad ati An-nasai).
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ka ilekoko ati aseju ninu esin kun oun ti ma ngbeni jade kuro ninu sunnah re ati ilana re. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
 " جاء ثلاثة رهط إلى بيوت أزواج النبي صلى الله عليه وسلم يسألون عن عبادة النبي صلى الله عليه وسلم فلما أخبروا كأنهم تقالوها فقالوا وأين نحن من النبي صلى الله عليه وسلم قد غفر الله له ما تقدم من ذنبه وما تأخر قال أحدهم أما أنا فإني أصلي الليل أبدا وقال آخر انا أصوم الدهر ولا أفطر وقال آخر أنا أعتزل النساء فلا أتزوج أبدا فجاء رسول الله صلى الله عليه وسلم فقال أنتم الذين قلتم كذا وكذا أما والله إني لأخشاكم لله وأتقاكم له لكني أصوم وأفطر وأصلي وأرقد وأتزوج النساء فمن رغب عن سنتي فليس مني "
'' awon eniyan meta kan wa si ile awon iyawo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), won nbeere nipa bi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se ma nse ijosin, nigba ti won fun won niro nipa ijosin re tan, o dabi enipe won foju kere re (ijosin re), won wa so bayi pe: kini awa je legbe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti Olohun ti se aforijin awon ese re yala eyi ti o ti koja tabi eyi ti yoo tun da. Eni akoko ninu won ba dahun wipe; e ri emi, ma ma fi gbogbo ale (oru) mi kirun lo lailai, enikeji si dahun wipe; emi yoo ma gba awe lo lailai mi o si ni sinu, eniketa naa si dahun wipe; ma jinna si awon obinrin mi o ni fe iyawo lailai.Beeni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wole bawon, o si sope: eyin le so bayi bayi! e teti yin, mo fi Olohun bura wipe emi ni eni ti o beru Olohun julo ninu yin, emi ni mo si paya re julo ninu yin, pelu bee naa mo ma ngba awe mo si ma nsinu, mo ma nkirun ni oru mo si ma nsun,mo si ma nfe iyawo,enikeni ti o ba pa ilana mi ti kii se ara (omoleyin) mi ''.
 Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti o ma tenumo oro naa fun awon omo leyin re ki won le jinna si ilana aseju ati ilekoko ninu esin. Abdullah omo A'maru omo Al-a's (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) sope; Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun mi pe:
" يا عَبْدَ اللَّهِ أَلَمْ أُخْبَرْ أَنَّكَ تَصُومُ النَّهَارَ وَتَقُومُ اللَّيْلَ فقلت بَلَى يا رَسُولَ اللَّهِ قال فلا تَفْعَلْ صُمْ وَأَفْطِرْ وَقُمْ وَنَمْ فإن لِجَسَدِكَ عَلَيْكَ حَقًّا وَإِنَّ لِعَيْنِكَ عَلَيْكَ حَقًّا وَإِنَّ لِزَوْجِكَ عَلَيْكَ حَقًّا وَإِنَّ لِزَوْرِكَ عَلَيْكَ حَقًّا وَإِنَّ بِحَسْبِكَ أَنْ تَصُومَ كُلَّ شَهْرٍ ثَلَاثَةَ أَيَّامٍ فإن لك بِكُلِّ حَسَنَةٍ عَشْرَ أَمْثَالِهَا فإن ذلك صِيَامُ الدَّهْرِ كُلِّهِ فَشَدَّدْتُ فَشُدِّدَ عَلَيَّ قلت يا رَسُولَ اللَّهِ إني أَجِدُ قُوَّةً قال فَصُمْ صِيَامَ نَبِيِّ اللَّهِ دَاوُدَ عليه السَّلَام ولا تَزِدْ عليه قلت وما كان صِيَامُ نَبِيِّ اللَّهِ دَاوُدَ عليه السَّلَام قال نِصْفَ الدَّهْرِ فَكَانَ عبد اللَّهِ يقول بَعْدَ ما كَبِرَ يا لَيْتَنِي قَبِلْتُ رُخْصَةَ النبي صلى الله عليه وسلم" البخاري
'' Ire Abdullah, iro de etigbo mi pe o ma nfi(gbogbo) osan gba awe o si ma nfi (gbogbo) oru kirun? Mo si dahun wipe beeni ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), o si dahun wipe: ma se bee mo, ma (fi igba kan) gba awe ki o si ma (fi igba miran) sinu, si ma (fi igba kan) kirun, ki o si ma (fi igba miran) sun. Nitoripe ara re ni iwo (eto) lori re, oju re naa ni iwo lori re, iyawo re ni iwo lori re, alejo re naa ni iwo lori re. O to fun o ki o ma gba awe meta meta ni osu kookan, nitoripe daadaa kan ti o ba se o fi gba esan mewa iru re, eleyi si tumo si awe odidi odun kan gbako. Mo taku, o si pada je inira fun mi! mo so pe ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) mo ni agbara ju bayi lo. O si dahun wipe: ma gba awe Anabi Dauda (ike ati ola Olohun ki o ma ba), o si gbodo se alekun re, mo wa beere wipe; bawo ni awe Anabi Dauda (ike ati ola Olohun ki o ma ba)? O si dahun wipe: idaji odun. Nigba ti Abdullah di agbalagba o ma nso pe: sio mi, se mi o ba si ti gba ede ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se fun mi '' (Al Bukhari).
 Eleyi ko tumo si pe esin Islam fe ki a wa aye moya ki a si teri dundun sinu ifekufe ati yodoyindin re. Esin Islam je esin aarin gungun (iwontun-wonsi) ti o se akojo laarin esin ati igbesi aye, ko gbe ola fun okan lona ti yoo pa ekeji lara. O pase iwontun-wonsi laarin emi ati ara, o si fe ki musulumi ma ranti awon oun ti o sopo mo emi ni asiko ti o ba nko airoju pelu awon oro aye, pelu ki o ma pe awon oun ti Olohun se ni oranyan le lori ninu awon ijosin, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نُودِيَ لِلصَّلَاةِ مِنْ يَوْمِ الْجُمُعَةِ فَاسْعَوْا إِلَى ذِكْرِ اللَّهِ وَذَرُوا الْبَيْعَ ذَلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ (9) "
''Eyin olugbagbo ododo, nigbati won ba perun ni ojo Jumah (akojo), e yara lo sibi iranti Olohun, ki e si fi rira-tita sile, eyi ni o dara fun yin ti o ba je pe e mo '' Q62:9.
Bakan naa ni o tun fe ki o ma ranti ni asiko ti o ba ko airoju pelu awon ise ijosin awon ojuse re ti o nise pelu isemi aye gegebi ona iwa ije ati imu. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" فَإِذَا قُضِيَتِ الصَّلَاةُ فَانْتَشِرُوا فِي الْأَرْضِ وَابْتَغُوا مِنْ فَضْلِ اللَّهِ "
'' Nitorinaa nigbati e ba pari irun naa tan, e fanka si ori ile ki e si ma wa kiri oore- ajulo Olohun '' Q62:10.
 Bakan naa ni o fi onde de ijegbadun pelu awon daradara pelu jijina si ina-apa, eyi ti aburu re lori ara ko pamo rara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَكُلُوا وَاشْرَبُوا وَلَا تُسْرِفُوا إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ (31) "
'' E ma je ki e si ma mu, ki e ma se na ina apa, dajudaju Oun Olohun ko nife awon oninakuna (onilokulo) '' Q7:31.
Atipe ki o le ba ye (fojuhan) wipe ko si iforigbari laarin awon oun ti esin nbeere lowo omoniyan ati eto isemi aye re ni Olohun ti ola Re ga se so bayi pe:
" لَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَنْ تَبْتَغُوا فَضْلًا مِنْ رَبِّكُمْ فَإِذَا أَفَضْتُمْ مِنْ عَرَفَاتٍ فَاذْكُرُوا اللَّهَ عِنْدَ الْمَشْعَرِ الْحَرَامِ وَاذْكُرُوهُ كَمَا هَدَاكُمْ وَإِنْ كُنْتُمْ مِنْ قَبْلِهِ لَمِنَ الضَّالِّينَ (198) "
'' Ko si ibawi fun yin lati wa ojure Oluwa yin. Nitorinaa bi e ba ndari bo lati Arafat ki e se iranti Olohun nibi aaye mimo naa (Muzdalifa), ki e se iranti Re gegebi oun ti se toyin s'ona bi o tile jepe ni saaju e wa ninu awon ti o s'onu '' Q2:198.
8- Ninu irorun esin Islam ni abala sise ofin naa tun ni pe, ti musulumi ba npaya iparun lori ara re, o leto lati je tabi mu ninu awon oun ti Olohun se ni eewo gegebi oku eran tabi eje eran tabi eran elede tabi oti ni deedee oun ti yoo gbe emi re ro. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةَ وَالدَّمَ وَلَحْمَ الْخِنْزِيرِ وَمَا أُهِلَّ بِهِ لِغَيْرِ اللَّهِ فَمَنِ اضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ (173) "
'' Dajudaju o se ni eewo fun; oku nbete ati eje ati eran elede ati oun ti a pe oruko miran le lori yato si ti Olohun. Sugbon eni ti inira ba mu (jee) ti ki i se ti ife inu re, ti ki i si se ti ikoja enu aala, ko si ese fun. Dajudaju Alaforijin ni Olohun, Alanu si ni '' Q2:173.
 Sayid Qutub (ki Olohun ki o ke) so ninu alaye ese oro yi pe: eleyi ni adisokan ti o se ifirinle ije eniyan omoniyan, ti ko gbe si ipo eranko tabi malaika tabi esu. O gbe omoniyan si ipo re ni ibamu si adamo re ni abala lile ati agbara, o mu gegebi nkankan ti a kojo latara ara ti o ni orisirisi onfa, ati lakaye ti o ni aponle, ati emi ti o ni awon oun ti o fe, won se awon ise kan ni oranyan fun ni eyi ti apa re ka, won si se agbekale laarin awon ojuse wonyi ati ikapani re ni ona ti ko mu inira tabi ifarani lowo ''
9- Ninu irorun esin Islam naa tun ni pe daadaa ti eniyan ba se yoo gba esan re ni ilopo-ilopo, sugbon ti eniyan ba se aburu ko ni gba ju esan ti o se deedee aburu ti o se naa lo, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" مَنْ جَاءَ بِالْحَسَنَةِ فَلَهُ عَشْرُ أَمْثَالِهَا وَمَنْ جَاءَ بِالسَّيِّئَةِ فَلَا يُجْزَى إِلَّا مِثْلَهَا "
'' enikeni ti o ba mu ise rere kan wa, mewa iru re yoo ma be fun un, eniti o ba si mu aburu kan wa a ko ni san ni esan ayafi iru re '' Q6:160.


IRORUN ESIN ISLAM NI ABALA IPEPE
Nitoripe esin Islam je esin gbogbo aye ti a fi ranse si gbogbo eniyan patapata ni gbogbo asiko ati ni gbogbo aaye, eleyi so di oranyan pe ki o gba iroyin pelu idekun ati irorun nibi ona ipepe re ati nibi sise agbekale re fun awon eniyan. Titi inife daadaa fun awon eniyan siwaju je okan ninu awon okunfa fifi aaye sile fun iforo-wero tabi isewadi ati gbigbafa awon eni ti a npe. Eleyi ni oju ona esin Islam nibi ipepe re, o pase ki a pe awon alatako pelu ogbon ati oye pelu waasi ti o dara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:     
" ادْعُ إِلَى سَبِيلِ رَبِّكَ بِالْحِكْمَةِ وَالْمَوْعِظَةِ الْحَسَنَةِ وَجَادِلْهُمْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ ".
''Pe ipe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ati waasi ti o dara ba won jiyan pelu eyi ti o dara (ni oro). '' Q16:125.
Ninu awon irorun esin Islam ni abala ipepe:
1- Ninu irorun esin Islam ni abala ni ipepe nipe o fi aaye sile fun gbogbo elesin miran ti o ba setan lati wo inu esin Islam bakan naa ni pe o ri si oun idunnu, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" لَلَّهُ أَشَدُّ فَرَحًا بِتَوْبَةِ عَبْدِهِ حين يَتُوبُ إليه من أَحَدِكُمْ كان على رَاحِلَتِهِ بِأَرْضِ فَلَاةٍ فَانْفَلَتَتْ منه وَعَلَيْهَا طَعَامُهُ وَشَرَابُهُ فَأَيِسَ منها فَأَتَى شَجَرَةً فَاضْطَجَعَ في ظِلِّهَا قد أَيِسَ من رَاحِلَتِهِ(دابته) فَبَيْنَا هو كَذَلِكَ إذا هو بها قَائِمَةً عِنْدَهُ فَأَخَذَ بِخِطَامِهَا ثُمَّ قال من شِدَّةِ الْفَرَحِ: اللهم أنت عَبْدِي وأنا رَبُّكَ أَخْطَأَ من شِدَّةِ الْفَرَحِ" مسلم
'' o ma ndun mo Olohun ninu pupo ki erusin Re ronupiwada wa si odo Re, ju bi inu enikookan yin se ma ndun nigba ti o ba wa ni ori nkan igun re ni ile okoo, ti nkan igun naa wa sonu mo lowo, ti o si jepe ori re ni onje ati omi re wa. Bayi ni o so ireti nu lori re, ti o si lo fi egbe lele labe ojiji igi kan ni eni ti o ti so ireti nu lori nkan igun naa. Sugbon laarin igba yi (bi o se laju) ni o ba a ti o duro ni egbe re, ni o ba gba ijanu re mu, leyin ni o ba so latari idunnu bayi pe: ire Olohun, iwo ni eru mi emi si ni oluwa re! o se asise latara idunnu '' (Muslim).
2- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe naa ni pe o pa awon olupepe lase pe ki won lo ilana fifi ife lole ati ifunni ni iro daadaa gegebi oju ona ipepe. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun asiwaju meji; Maa'dh omo Jabal pelu Abu Musa Al-asha'ri (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) nigba ti o ran won lo si ile Yamani fun ise ipepe, bayi pe:
" بشرا ولاتنفرا ويسرا ولاتعسرا وتطاوعا ولاتختلفا"(أحمد، والبخارى، ومسلم)
'' e ma fun won ni iro-idunnu, e ma se le won seyin (pelu iro ibanuje ati ideruba), e ma se irorun e ma mu nkan le koko, e ma gboro si ara yin lenu e ma se iyapa enu '' (Ahmad, Al Bukhari, Muslim).
3- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe naa tun ni pe o pa awon olupepe lase pe ki won se iforo-wero pelu awon alatako ni ibamu si ilana ti o se aponle lakaye pelu akolekan ipo won, eleyi ti ko mu iyepere tabi imunisere dani. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلَا تُجَادِلُوا أَهْلَ الْكِتَابِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِلَّا الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ وَقُولُوا آمَنَّا بِالَّذِي أُنْزِلَ إِلَيْنَا وَأُنْزِلَ إِلَيْكُمْ وَإِلَهُنَا وَإِلَهُكُمْ وَاحِدٌ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ (46) "
'' E ko gbodo ba awon oni Tira jiyan ayafi ni ona ti o dara julo, ayafi awon eniti o se abosi ninu won. Atipe ki e so bayi pe; awa gbagbo ni ododo oun ti o sokale fun wa ati oun ti o sokale fun yin, atipe Olohun wa ati Olohun yin okansoso ni, Oun ni awa jowo-juse sile fun '' Q29:46.
 A kii fi tipatipa gba irori (esin Islam) a kii si muni ni dandan lati gba ilana tabi ko o sile, bikosepe ki a teti si awon eri ati awijare, ki a si fi oro wero lati lati moo dodo. Ninu awon ona ti a ma nlo lati se iforo-wero pelu awon ti kii se elesin Islam ni ilana ibalakaye soro ati fifi ogbon ati oye salaye oro ni ona ti o ba ironu eniti a nba soro dogba.
 Ninu apejuwe ilana yi ni oro ajinde leyin iku; omo A'baas (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) sope:
جاء العاص بن وائل – وهو غير مسلم - إلى رسول الله صلى الله عليه وسلم بعظم حائل ففته فقال: يا محمد أيبعث الله هذا بعد ما أرم؟! قال:" نعم يبعث الله هذا يميتك ثم يحييك ثم يدخلك نار جهنم" قال: فنزل فقول الله تعالى:" أَوَلَمْ يَرَ الْأِنْسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِنْ نُطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُبِينٌ * وَضَرَبَ لَنَا مَثَلاً وَنَسِيَ خَلْقَهُ قَالَ مَنْ يُحْيِي الْعِظَامَ وَهِيَ رَمِيمٌ * قُلْ يُحْيِيهَا الَّذِي أَنْشَأَهَا أَوَّلَ مَرَّةٍ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ * الَّذِي جَعَلَ لَكُمْ مِنَ الشَّجَرِ الْأَخْضَرِ نَاراً فَإِذَا أَنْتُمْ مِنْهُ تُوقِدُونَ * أَوَلَيْسَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِقَادِرٍ عَلَى أَنْ يَخْلُقَ مِثْلَهُمْ بَلَى وَهُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ"(رواه الحاكم وقال هذا حديث صحيح على شرط الشيخين و لم يخرجاه)
Al-Aa's omo Waail (o si je eni ti kii se musulumi) wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pelu egungun ti o ti kefun, o si so bayi pe; ire Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nje Olohun yoo gbe eleyi dide bi leyin ti o ti kefun? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe; '' beeni Olohun yoo gbe e dide, yoo si pa iwo naa, leyin naa yoo gbe o dide, leyin naa yoo si fi o wo sinu ina jahanamah '' o sope bayi ni oro Olohun so kale bayi pe: ''Se omoniyan ko wa mo ni pe Awa ni A da oun lati inu omi logbologbo? Nigbanaa oun wa je atako ti o han gbangba \\ Atipe o se apejuwe fun wa o si gbagbe eda re, o wa so bayi pe: Tani yoo ji egungun ti o ti kefun? \\ Sope: Eni ti o se eda re nigba akoko naa ni yoo ji i dide, Oun si ni Onimimo nipa gbogbo eda. \\ Eniti O mu ina jade latara igi tutu fun yin, nigba naa ni eyin si nwa mfi ko ina. \\ Nje Eniti O da sanma ati ile ko wa lagbara lati da iru won bi? Beeni, Oun ni O da awon eda, (oun si ni) Onimimo '' Q36:78-81., (Al-Hakim).
 Iru awon iforo-wero bayi ati ida-oro-pada-sini-lenu pelu ogbon ati oye pelu awon eri ti o duro to ati alaye ti ko ni iruju ninu rara, eyi ti kii fi aaye sise iyemeji sile fun awon ti o ba ni lakaye ti o pe, ti won si je eniti nwa ododo, mo nse afinrile pe esin Islam ni esin ododo, ti o si leto ki a mu ni oju ona. Eleyi si ni ilana ti o ma bori ni igbeyin. Olohun ti ola Re ga so nipa itan iforo-wero ti o waye laarin Anabi Ibraheem (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ati oba Baabil tii se Namruudu omo Kanaa'n, ti o lo bayi pe:
...:" أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِي حَاجَّ إِبْرَاهِيمَ فِي رَبِّهِ أَنْ آتَاهُ اللَّهُ الْمُلْكَ إِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّيَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا أُحْيِي وَأُمِيتُ قَالَ إِبْرَاهِيمُ فَإِنَّ اللَّهَ يَأْتِي بِالشَّمْسِ مِنَ الْمَشْرِقِ فَأْتِ بِهَا مِنَ الْمَغْرِبِ فَبُهِتَ الَّذِي كَفَرَ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (258) " البقرة 258
'' Iwo ko ha woye nipa eni ti o nba Ibraheem Jiyan nipa Oluwa re nitoripe Olohun ti fun ni ijoba (O se ni oba), nigba ti Ibraheem sope: Oluwa mi ni o ma nseni ni emi oun ni o si ma (nfi iku) pa ni, o si sope 'emi ma nseni ni emi mo si ma npa ni'. Ibraheem sope: Dajudaju Olohun ni O ma nmu oorun wa lati ila-oorun, nje iwo mu wa lati iwo-oorun. Bayi ni A ko idaamu ba eni ti ko gbagbo naa. Olohun kii to awon alabosi eniyan sona '' Q2:258.
4- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe naa tun nipe o jinna tefetefe si ilana eebu, ifi abuku kan ni, ifinise-yeye ati awon orisirisi ida-wahala sile ati ifini-sesin. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَقُلْ لِعِبَادِي يَقُولُوا الَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِنَّ الشَّيْطَانَ يَنْزَغُ بَيْنَهُمْ إِنَّ الشَّيْطَانَ كَانَ لِلْإِنْسَانِ عَدُوًّا مُبِينًا" الإسراء 53
'' So fun awon erusin Mi pe ki won maa so eyi ti o dara julo (ninu oro). Dajudaju esu yoo maa da iyapa si aarin won. Dajudaju esu je ota ti o fojuhan gbangba si omoniyan '' Q17:53.
5- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe naa tun ni lilo ilana fifi ife, aanu, ati ike lole ninu eni ti a fe pe, eleyi ti o gba ki a lo ilana ti o ma nje ki okan fa mo oun ti a npe e si, pelu awon ti o le ti o ma bi ife sinu okan. Olohun ti ola Re ga so bayi pe
" يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لِمَ تُحَاجُّونَ فِي إِبْرَاهِيمَ وَمَا أُنْزِلَتِ التَّوْرَاةُ وَالْأِنْجِيلُ إِلَّا مِنْ بَعْدِهِ أَفَلا تَعْقِلُونَ "
'' Eyin-onitira kilo de ti e fi n jiyan nipa Ibraheem, beeni A ko so At-taoreta ati Injila kale (loju re) bikose leyin re, eyin ko wa se lakaye ni '' Q3:65.
6- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe tun ni sisoro pelu pelepele ati jijinna si ile koko mo eni ti a npe. Olohun ti ola Re ga, nigba ti O ran Anabi Musa ati omo iya re Haruna (ike ati ola Olohun ki o ma ba awon mejeeji) si odo Firiaona (eni ti o pe ara re ni Olohun ti o so pe ki awon eniyan maa josin fun oun) fun ise ipepe so bayi pe:
" اذْهَبَا إِلَى فِرْعَوْنَ إِنَّهُ طَغَى* فَقُولا لَهُ قَوْلاً لَيِّناً لَعَلَّهُ يَتَذَكَّرُ أَوْ يَخْشَى"
'' ki eyin mejeeji ba soro pelepele, o le je pe yoo ronu tabi ki o beru '' Q20:44.
7- Ninu irorun esin islam ni abala ipepe tun ni bi o se ma nfe lati je ki awon ti won kii se elesin Islam ti ajo nse iforo-weroma se afihan awon awijare ati awon eri won, bakan naa lati ma fun won ni anfaani lati salaye oun ti nbe ni odo won, ki a le jo foro-jomi-toro-oro lori re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قُلْ أَرَأَيْتُمْ مَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ ائْتُونِي بِكِتَابٍ مِنْ قَبْلِ هَذَا أَوْ أَثَارَةٍ مِنْ عِلْمٍ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ".
'' Sope: se e ko wa ri oun ti e npe leyin Olohun bi? E fi han mi kinni won da ni ori ile, abi ikopa kankan nbe fun won ninu (dida) sanma naa ni? E mu Tira kan ti o ti saaju eyi wa, tabi aseku mimo kan ti eyin ba je olododo ''Q46:4.
8- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe ni bi o se ma nfe ki awon ti kii se elesin Islam ti a nba foro we'ro ni afojusun kan naa pelu wa, leyi ti yoo fun wa ni anfaani ki oro wa sokan ni ibamu si ilana ti Olohun ti o wa lori ife ati inife daadaa fun ara eni, yato si ilana setie-kin-setemi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إِلَى كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ أَلَّا نَعْبُدَ إِلَّا اللَّهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِ شَيْئًا وَلَا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ (64) "
'' Sope; eyin Oni-Tira (ti a fun ni majemu lai lai ati mojemu tuntun) e wa sibi gbolohun oro kan ti o dogba laarin wa ati laarin yin, pe ki awa ma se sin nkan miran leyin Olohun, ki awa ma si se wa orogun kan pelu Re, ki apakan wa ma se mu apakeji ni oluwa leyin Olohun; sugbon bi eyin ba peyin da, e wipe; e jeri pe musulumi ni awa se '' Q3:64.
9- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe naa tun ni pe o fi aaye sile fun gbogbo eni ti o ba fe darapo mo esin Islam lai ni wahala, idaamu, inira tabi ayeye kan ti agbodo se ni aaye kan lodo awon asayan eniyan kan. Eleyi ri bee nitoripe o je esin kan ti o mu asepo waye laarin erusin ati Oluwa re lai ni alagata ninu. Gbolohun ti o rorun pupo ni siso ati itumo ti eni ti o ba gbero lati di musulumi yoo so ti yoo si di elesin musulumi, gbolohun naa ni gbolohun ijeri;
( أشهد أن لا إله إلا الله وأشهد أن محمداً عبد الله ورسوله )
'' mo jeri pe ko si enikankan ti o leto si ijosin ayafi Olohun, atipe dajudaju Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eru Olohun ati ojise Re ''. Eleyi si ni kokoro wiwole sinu esin Islam, enikeni ti o ba so eleyi ni ti ododo ti bora kuro nibi gbogbo esin tabi adisokan ti o yato si esin Islam, o si ni eto si ohunkohun ti awon musulumi ba ni eto si, bakan naa ni o di eewo fun awon ti o je eewo fun awon musulumi.
10- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe tun ni pe, Olohun yoo se aforijin gbogbo ese ti enikeni ti o ba darapo mo esin Islam ti da siwaju ki o to di musulumi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قُلْ لِلَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ يَنْتَهُوا يُغْفَرْ لَهُمْ مَا قَدْ سَلَفَ "
'' So fun awon alaigbagbo pe ti won ba jawo A o se aforijin awon ese won ti o ti siwaju '' Q8:38.
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" الإسلام يجب (أي يهدم ويمحو ويزيل) ما قبله والتوبة تجب ما كان قبلها " رواه أحمد وهو صحيح
'' Esin Islam ma nse apare awon ese ti o siwaju re, bakan naa ni ironupiwada ma nse apare awon ese ti o siwaju '' (Ahmad).
11- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe tun ni pe, enikeni ti o ba di musulumi ninu eni ti kii se elesin Islam tele yoo gba esan daadaa lori awon ise rere ti o ti se siwaju ki o to di musulumi. Hakeem omo Hizaam (Olohun ki o yonu si) so bayi pe:
" قلت: يا رَسُولَ اللَّهِ أَرَأَيْتَ أَشْيَاءَ كنت أَتَحَنَّثُ(أتعبد) بها في الْجَاهِلِيَّةِ من صَدَقَةٍ أو عَتَاقَةٍ وَصِلَةِ رَحِمٍ فَهَلْ فيها من أَجْرٍ؟ فقال النبي صلى الله عليه وسلم:" أَسْلَمْتَ على ما سَلَفَ من خَيْرٍ" البخاري
'' mo so pe; ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), nje awon nkan ti mo fi ma nse ijosin nigba aimokan gegebi itore aanu, bibokun lorun eru, ati mimo da molebi po, se mo wa ni esan lori re bi? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si da lohun wipe; o gba Islam lori daadaa ti o ti siwaju ni '' (Al Bukhari).
12- Ninu irorun esin Islam ni abala ipepe tun ni pe, enikeni ti o ba di musulumi ninu awon ti kii se elesin Isam tele (awon Oni-Tira) yoo gba esan re ni ilopo meji latara ini igbagbo won si Ojise won ati ini igbagbo won si Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِهِ هُمْ بِهِ يُؤْمِنُونَ (52) وَإِذَا يُتْلَى عَلَيْهِمْ قَالُوا آمَنَّا بِهِ إِنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّنَا إِنَّا كُنَّا مِنْ قَبْلِهِ مُسْلِمِينَ (53) أُولَئِكَ يُؤْتَوْنَ أَجْرَهُمْ مَرَّتَيْنِ بِمَا صَبَرُوا وَيَدْرَءُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ (54) "
'' Awon eni ti A fun ni Tira siwaju re, won ni igbagbo ododo si i \\ Atipe nigba ti A ba ke fun won won ma nsope; Awa ni igbagbo si i. dajudaju ododo ni lati odo Oluwa wa, dajudaju awa ti je eni ti o ju-owo-ju-ese sile fun Olohun siwaju re \\ Awon wonyi ni A o fun ni easn won ni eemeji, nitori ifarada won, atipe won nfi (iwa) rere ti buburu seyin, atipe won nna ninu oun ti A fun won '' Q28:52-54.

IRORUN ESIN ISLAM NI ABALA IBASEPO PELU ENI TI KI I SE MUSULUMI
 Oro wa pelu awon ti kii se elesin Islam lori irorun esin Islam yoo bere pelu oro olukeko esin Islam ti kii se musulumi kan ti oruko re nje Louis Young, lati le je abawole sinu oro lori awon apakan irorun ati irora esin Islam pelu awon ti kii see elesin Islam. O so bayi pe:
''Dajudaju awon oun ti o po repete ni ile Geribu (Oyinbo) ni lati ko ninu awon olaju esin Islam, okan ninu re si ni ' iwoye larubawa lori idekun ati irora ''
1- Ninu irorun esin Islam pelu awon ti kii se elesin Islam ni pe, o se ni eto lati ba won se asepo ninu gbogbo asepo ti o je mo owo, gegebi tita ati rira, jijo da owo papo, ati gbogbo iran owo-sise ni ibamu si ilana ofin esin Islam, eyi ti yoo jinna si ifarani ara-eni, ti yoo si so iwo onikaluku pelu iyonu ati ini imo si oun ti a fe ta tabi ra ni ibamu si awon mojemu re. Aisha (Olohun ki o yonu si) gba wa pe:
" أَنَّ النبي صلى الله عليه وسلم اشْتَرَى طَعَامًا من يَهُودِيٍّ إلى أَجَلٍ فَرَهَنَهُ دِرْعَهُ " البخاري
 Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ra ounje lowo arakunrin elesin yehudi kan ni awin, o si fi aso ogun re dogo si ni odo '' (Al Bukhari).
Esin Islam ko se nkankan ni eewo ninu ajosepo yi ayafi oun ti o ba mu inira, abosi gegebi jije ele (riba), ati tete tita dani, awon eleyi je eewo fun mususlumi ati eni ti kii se musulumi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَأْكُلُوا الرِّبَا أَضْعَافًا مُضَاعَفَةً وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ " آل عمران 130
'' Eyin onigbagbo ododo, e ma se je ele (riba), adipele lori adipele. Ki e si beru Olohun ki e le ba se orire '' Q3:130.
Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالْأَنْصَابُ وَالْأَزْلَامُ رِجْسٌ مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ (90) إِنَّمَا يُرِيدُ الشَّيْطَانُ أَنْ يُوقِعَ بَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ فِي الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ وَيَصُدَّكُمْ عَنْ ذِكْرِ اللَّهِ وَعَنِ الصَّلَاةِ فَهَلْ أَنْتُمْ مُنْتَهُونَ (91) "
''Eyin onigbagbo ododo, dajudaju oti ati tete-tita ati orisa-bibo ati fifi ofa pin nkan, egbin ni ninu ise esu, nitorinaa e jinna si, ki e le ba se orire \\ Esu nfe lati da ota ati ikorira sile laarin yin, nipa oti ati tete-tita, ati ki o le ko di yin lona kuro nibi iranti Olohun ati kuro nibi irun kiki, nje e o ha siwo bi? '' Q5:90-91.
2- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se musulumi naa tun ni pe, o se kiki irun ni eto ni awon ile ijosin won. Won gba wa pe Abu Musa ki irun ninu soosi Damasikosi ti won npe ni Soosi Nahya. (Musonaf Ibn Abi Shaybah). Bi o tile jepe won korira ki a se be nigba ti awon aworan ati ere ba wa ni inu soosi ti a ko si ri ibomiran.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se musulumi naa tun ni pe, o se ki won wo inu masalasi ni eto fun won fun awon idi pataki tabi fun anfaani kan ayafi masalasi ilu Makkah. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti o ma ngba alejo awon iko orisirisi ninu awon ti won kii se elesin Islam si inu masalasi re ni ilu Modinah, ti kii si kofun won lati wo inu re. Koda Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun de Thumamah omo Aathaal (Olohun ki o yonu si) mole si inu masalasi ilu Modinah siwaju ki o to di musulumi.
4- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se ima be alaisan won wo ni eto, ki a si se adua fun won pe ki Olohun se alafia fun won. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
" كان غُلَامٌ يَهُودِيٌّ يَخْدُمُ النبي صلى الله عليه وسلمفَمَرِضَ فَأَتَاهُ النبيصلى الله عليه وسلميَعُودُهُ فَقَعَدَ عِنْدَ رَأْسِهِ فقال له:" أَسْلِمْ " فَنَظَرَ إلى أبيه وهو عِنْدَهُ فقال له: أَطِعْ أَبَا الْقَاسِمِصلى الله عليه وسلمفَأَسْلَمَ فَخَرَجَ النبي صلى الله عليه وسلموهو يقول:" الْحَمْدُ لِلَّهِ الذي أَنْقَذَهُ من النَّارِ" البخاري.
'' odomokunrin yehuudi kan nbe ti o ma nba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se awon ise ile, nigba ti o nse aisan, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) be e wo, o joko sibi ori re o si so bayi pe: gba Islam (di elesin Islam) '' omo yi wo oju baba re ti nbe ni odo re, baba re si so fun pe: se oun ti baba Qaasim (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni ki o se. Bayi ni omo yi di musulumi. Nigba ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) jade ni odo re o si bere si ni so pe: ope ni fun Olohun ti o yo kuro ninu ina '' (Al Bukhari).
5- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se iba won kedun ni eto nigba ti eniyan ba pa ipo da. Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) gba wa pe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" استأذنت ربي أن أستغفر لأمي فلم يؤذن لي واستأذنته أن أزور قبرها فأذن لي " مسلم
'' mo toro iyonda ni odo Oluwa mi lati toro aforijin fun iya mi, sugbon ko yonda fun mi, mo toro ki O yonda fun mi lati be saare re wo, O si yonda fun mi '' (Muslim).
6- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elsin Islam tun ni pe o se leto ki a se itore-aanu ati ki a fun won ni ebun nigba ti won ko ba gbogun ti wa. Won pa eran ewure fun awon ara ile Abdullah omo Umar ni ojo kan, nigba ti o de o beere wipe: nje e ti fun Yehuudi ti se alabagbe wa nibe bi? Mo gbo ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" ما زال جبريل يوصيني بالجار حتى ظننت أنه سيورثه "مُتَّفَقٌ عَلَيهِ
'' Jubreel ko-ye ko- gbo ni eni ti nso asotele fun mi nipa alabagbe mi titi ti mo fi ro pe yoo pin ninu ogun re (alabagbe re) '' (Al Bukari ati Muslim).
 Nibi ti oro alabagbe ni agbara de, esin islam se ni eto ki a fun alabagbe eni, ti o wa ninu awon ti a fe jere okan won, ni zakat eyi ti o je eto awon alaini ninu musulumi, nigba ti anfaani ba wa fun awon musulumi nibi fifun won (alabagbe ti kii se musulumi) ni zakat naa, tabi yoo je okunfa wiwo inu esin Islam won tabi yoo je ki won le daabo tabi gbarata fun esin Islam. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
". إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاءِ وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (60) التوبة 60
'' Ore (zakat) wa fun awon talika ati awon alaini ati awon ti nsise re ati awon ti a nfa okan won mora (sinu Islam) ati fun irapada awon eru ati awon ti o je gbese ati si oju ona ti Olohun ati omo oju-ona, oranyan ni lati odo Olohun, Olohun ni Olumo Ojogbon '' Q9:60.
Umar omo Abdul Azeez sope: o de etigbo mi pe Umar omo Khattab ri arakunrin kan ti kii se elesin Islam sugbon ti o ngbe ni ilu mususlumi ti o ntoro kaakiri ile awon musulumi, Umar si so pe: a ko se deedee pelu re, won gba owo-ori lowo re nigba ti o wa ni odo sugbon won wa pa o ti ni asiko yi! bayi ni Umar pase ki won pese ounje fun un lati ile owo musulumi ''(Al-kashfu wa Al-bayaan).
7- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam naa tun ni pe, o se dida okun ibi po laarin musulumi ati awon ti kii se musulumi ninu molebi re ni eto.
فعن أَسْمَاءَ بِنْتِ أبي بَكْرٍ رضي الله عنهما قالت قَدِمَتْ عَلَيَّ أُمِّي وَهِيَ مُشْرِكَةٌ في عَهْدِ رسول اللَّهِ صلى الله عليه وسلم فَاسْتَفْتَيْتُ رَسُولَ اللَّهِ صلى الله عليه وسلم قلت إن أمي قدمت وَهِيَ رَاغِبَةٌ أَفَأَصِلُ أُمِّي قال نعم صِلِي (صلة الرحم) أُمَّكِ" البخاري.
 Asmau omo Abu Bakri (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) so pe: iya mi wa si odo mi, ti o si jepe osebo ni ni asiko Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), mo wa bi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) leere bayi pe: dajudaju iya mi wa si odo mi fun nkan kan, se ki n da ibi re po (se daadaa si)? o si dahun wipe; beeni, da ibi iya re po (se daadaa si) '' (Al Bukhari).
8- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se ounje jije ninu awon oun elo won (abo, ife abbl) ni eto niwon igba ti won ko ba lo fun oun eewo gegebi elede ati oti mimu, bakan naa o tun se aso won ni wiwo ni eto niwonba igba ti won ko ba se latara awon eewo gegebi ife ti won se latara wura (goolu) tabi fadaka tabi awo elede tabi aja.
 Awon nkan wonyi je eewo ti ko leto fun lilo koda ki o jepe musulumi ni o ni won. Abu tha'labah Al-khushaniy so bayi pe:
 يا رسول الله إنا بأرض قوم أهل كتاب أفنأكل في آنيتهم ؟ قال: " إن وجدتم غيرها فلا تأكلوا فيها، وإن لم تجدوا فاغسلوها وكلوا فيها" رواه البخاري.
'' iwo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), inu ilu awon ijo Oni-Tira ni awa wa, se a le je ounje ninu abo won bi? O si dahun wipe: ti e ba ri omiran e ma se fi jeun, sugbon ti e ko ba ri omiran e foonu ki e wa fi jeun '' (Al Bukhari).
9- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se ni eto lati fe ninu awon obinrin Oni-Tira gegebi o se se ounje won jije ni eto, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" الْيَوْمَ أُحِلَّ لَكُمُ الطَّيِّبَاتُ وَطَعَامُ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ حِلٌّ لَكُمْ وَطَعَامُكُمْ حِلٌّ لَهُمْ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الْمُؤْمِنَاتِ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِكُمْ إِذَا آتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ مُحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَافِحِينَ وَلَا مُتَّخِذِي أَخْدَانٍ " المائدة 5
'' Loni yi A se ni eto fun yin gbogbo oun ti o dara. Ati ounje awon eni ti A fun ni Tira ni A se leto fun yin A si se ounje ti yin naa ni eto fun won. Ati awon obinrin omoluwabi ninu awon onigbagbo ododo ati awon obinrin omoluwabi ninu awon ti A ti fun ni Tira siwaju yin, nigba ti e ba ti fun won ni owo-ife won, ni ti fife ni iyawo ti kii se ti pansaga tabi mimu (won) ni ale '' Q5:5.
10- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, ise afirinle igbeyawo eni ti o ba se igbeyawo siwaju ki o to di musulumi, ni ibamu si isesi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pelu gbogbo eni ti o gba Islam ninu awon eni ti won kii se musulumi tele. Gaylaanomo Salamah At-thaqafiy di musulumi ti o si je pe obinrin mewa ni o je iyawo re ni ojo naa, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa so fun pe:
" اختر منهن أربعا" الترمذي وحسنه الألباني في الإرواء: 1885
'' se esa merin pere ninu won '' (At tirmidhi).
11- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se jije eran ti awon Oni-Tira nikan ba pa (du) ni eto nigba ti won ba daruko Olohun si. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلَا تَأْكُلُوا مِمَّا لَمْ يُذْكَرِ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ وَإِنَّهُ لَفِسْقٌ ".
'' Atipe e ko gbodo je ninu oun (eran) ti won ko daruko Olohun le lori, nitoripe dajudaju o je ibaje '' Q6:121.
12- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se ni eto ki a daabo bo won ki a si fi won lokan bale, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَإِنْ أَحَدٌ مِنَ الْمُشْرِكِينَ اسْتَجَارَكَ فَأَجِرْهُ حَتَّى يَسْمَعَ كَلَامَ اللَّهِ ثُمَّ أَبْلِغْهُ مَأْمَنَهُ "(التوبة:6)
'' Ti enikan ninu awon ti o da nkan po mo Olohun ba wa abo re, ki o daabo bo o titi ti yoo fi ma gbo oro Olohun, leyin naa ki o si mu de aaye ifayabale re '' Q9:6.
13- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, enikeni ti o ba se ibaje (pa eniyan) ninu won si iha odo mususlumi, ti o si la ki won lo ofin ipaniyan le lori ninu ilu awon mususlumi lo, won yoo fun awon ti won pa eniyan won ni anfaani lati sesa ninu awon nkan meta; ki won se amojukuro fun, tabi ki won gba owo- emi lowo re, tabi ki won lo ofin ipaniyan le lori. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَكَتَبْنَا عَلَيْهِمْ فِيهَا أَنَّ النَّفْسَ بِالنَّفْسِ وَالْعَيْنَ بِالْعَيْنِ وَالْأَنْفَ بِالْأَنْفِ وَالْأُذُنَ بِالْأُذُنِ وَالسِّنَّ بِالسِّنِّ وَالْجُرُوحَ قِصَاصٌ فَمَنْ تَصَدَّقَ بِهِ فَهُوَ كَفَّارَةٌ لَهُ " المائدة 45.
'' Awa ti se ni ofin ninu re fun won pe ti emi kan ba pa emi kan ki won pa a dipo re, atipe ti enikan ba fo elomiran loju, ki won fo tire naa, atipe ti enikan ba re elomiran ni imu, ki won re tire naa, atipe ti enikan ba gee elomiran leti, ki won ge tire naa, atipe ti enikan ba yo ehin elomiran, ki won yo tire naa, ati sisa ogbe pelu bakan naa ni gbigba esan. Enikeni ti ko ba gba esan yoo je itaran fun un '' Q5:45.
14- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se ni oun aito ki awon musulumi maa fi enu ete, iyepere, ati abuku kan esin won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe
" وَلَا تَسُبُّوا الَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ فَيَسُبُّوا اللَّهَ عَدْوًا بِغَيْرِ عِلْمٍ "
'' E ma se ma bu awon oun ti won npe leyin Olohun nitori ki won ma bu Olohun ni ti abosi pelu aimokan '' Q6:108.
15- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se pipe adehun tita-rira pelu won ni oranyan, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَوْفُوا بِالْعُقُودِ " المائدة:1
'' Eyin onigbagbo ododo, e ma pe awon adehun '' Q5:1.
Bakan naa ni o tun se pipe adehun ati ileri fun won ni oranyan, ti osi se yiye adehun ni eewo, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَأَوْفُوا بِالْعَهْدِ إِنَّ الْعَهْدَ كَانَ مَسْئُولًا "
'' E ma pe awon ileri, dajudaju ileri je oun ti A beere nipa re '' Q17:34.
16- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se dukia won, emi won ati omoluwabi (iyi) won ni oun owo (aponle). Eewo lo je ki a se abosi si won tabi ki a gboju ota si won pelu didin awon eto won ku tabi ki a ba won lo ni ona ti ko dara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" لَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُمْ مِنْ دِيَارِكُمْ أَنْ تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ (8) "
'' Olohun ko ko fun yin nipa awon eniti won ko ba yin jagun nipa esin ti won ko si le yin jade kuro ninu ile yin, pe ki e mase oore fun won ati ise deedee si won. Dajudaju Olohun feran awon oluse deedee '' Q60:8. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:
" ألا من ظلم معاهداًأو انتقصهأوكلّفه فوق طاقتهأو أخذ منه شيئاً بغير طيب نفس فأنا حجيجه يوم القيامة "صححه الألباني في الصَّحِيحَة: 445
'' E teti yin, enikeni ti o ba se abosi si eni ti a ba ni adehun alaafia, tabi o fi abuku kan-an, tabi o yan-an ni ise ti agbara re ko ka, tabi o gba dukia re pelu ai dunnu re, emi ni maa gba ejo ro fun ni ojo ajinde '' (As silsilatu As saheehah). Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun so pe:
" من قَتَلَ مُعَاهَدًا لم يَرِحْ رَائِحَةَ الْجَنَّةِ وَإِنَّ رِيحَهَا تُوجَدُ من مَسِيرَةِ أَرْبَعِينَ عَامًا" البخاري (حجيجه: من المحاجة: المغالبة وإظهار الحجة).
'' Enikeni ti o ba pa eni ti a ba ni adehun alafia, ko ni gbo oorun ogba idera (Al-jannah), ti o si jepe oorun re yoo ma je gbigbo lati oun ti o to irin ajo ogoji odun '' (Al Bukhari).
17- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o se ni ojuse ijoba ilu musulumi lati pese eto igbaye-gbadun fun awon ti kii se elesin Islam ti won ngbe ni inu ilu ti nlo eto ijoba ti ilana esin Islam. Eleyi je isesi Arole eleekeji leyin Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) Umar omo Khattab (Olohun ki o yonu si), nigba ti o ri baba arugbo kan ti o je yehuudi ti ntoro itore-aanu lowo awon eniyan. Nigba ti o beere nipa baba arugbo yi o ri pe okan ninu awon ti ma san owo-ori ni, ni o ba so bayi pe:
 ما أنصفناك إن أخذنا الجزية منك في شبابك وضيعناك في كبرك فأخذ بيده إلى بيته وأعطاه ما وجد من الطعام واللباس، ثم أرسل إلى خازن بيت المال يقول له: انظر إلى هذا وأمثاله فأعطهم ما يكفيهم وعيالهم من بيت مال المسلمين فإن الله سبحانه يقول:" إنما الصدقات للفقراء والمساكين " والفقراء هم المسلمونوالمساكين هم أهل الكتاب
'' a ko se deedee pelu re, nigba ti o je pe a gba owo-ori lowo re nigba ti o wa ni odo sugbon a wa pa o ti nigba ti o darugbo. Bayi ni o mu baba yi lo si ile re ti o si fun ni ounje ati aso. Leyin naa ni o tun ranse si alamojuto ile-owo musulumi ti o si so fun un pe: wo iru baba arugbo yi ati awon ti o ba joo, ri pe o nfun won ni oun ti yoo to won ati awon ara ile won ninu ile-owo musulumi, nitoripe Olohun ti O mo ganga so bayi pe: '' Ore (zakat) wa fun awon talika ati awon alaini '' awon talika awon ni awon musulumi, nigba ti awon alaini je awon Oni-Tira ''
18- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam tun ni pe, o pa awon musulumi lase pe ki won se amojukuro fun awon ti o ba gboju ota ninu awon ti kii se elesin Islam nigba ti owo ba te won, lati le fi aanu esin Islam han ati lati fa okan mora, bakan naa lati je ki won mo pe esin ike ati ife ni esin Islam ti o si jinna si ile koko ati ifiya jeni nigba ti o ba ri anfaani lati se bee. Olohun ti ola Re ga so fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) bayi pe:
" فَبِمَا نَقْضِهِمْ مِيثَاقَهُمْ لَعَنَّاهُمْ وَجَعَلْنَا قُلُوبَهُمْ قَاسِيَةً يُحَرِّفُونَ الْكَلِمَ عَنْ مَوَاضِعِهِ وَنَسُوا حَظًّا مِمَّا ذُكِّرُوا بِهِ وَلَا تَزَالُ تَطَّلِعُ عَلَى خَائِنَةٍ مِنْهُمْ إِلَّا قَلِيلًا مِنْهُمْ فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاصْفَحْ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ (13) " المائدة 13
'' Sugbon nitori yiye ti won ye mojemu Awa se ibi le won Awa si je ki okan won le. Won si nyi awon oro (Olohun) pada kuro ni awon aaye won, won si ko apakan sile ninu oun ti A ran won leti re. Iwo ko ni ye ri iwa ibaje lati odo won ayafi die ninu won, nitori naa se amojukuro fun won ki o si se aforijin. Dajudaju Olohun feran awon ti nse rere '' Q5:13.
Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:
" وَدَّ كَثِيرٌ مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ لَوْ يَرُدُّونَكُمْ مِنْ بَعْدِ إِيمَانِكُمْ كُفَّارًا حَسَدًا مِنْ عِنْدِ أَنْفُسِهِمْ مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ الْحَقُّ فَاعْفُوا وَاصْفَحُوا حَتَّى يَأْتِيَ اللَّهُ بِأَمْرِهِ إِنَّ اللَّهَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (109) "البقرة 109
'' Opolopo awon Oni-Tira ni won nfe lati da yin pada si ipo aigbagbo lehin igbagbo yin, ni ti egan lati odo won lehin igba ti otito ti han si won, nitori naa se aforijin fun won ki o si gunri kuro ni odo won titi ti Olohun yoo fi mu ase Re wa, dajudaju Olohun ni agbara lori gbogbo nkan '' Q2:109. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قُلْ لِلَّذِينَ آمَنُوا يَغْفِرُوا لِلَّذِينَ لَا يَرْجُونَ أَيَّامَ اللَّهِ لِيَجْزِيَ قَوْمًا بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ" الجاثية 14
'' So fun awon onigbagbo ododo wipe ki won mojukuro fun awon ti ko beru awon ojo Olohun, ki O le san esan fun awon eniyan kan nibamu si oun ti won se '' Q45:14.
19- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se elesin Islam naa tun ni pe, o se ilana pipe won si oju ona esin ni eyi ti o dara, o si fi aaye sile fun irankan daadaa lori won ati mimo ran won leti aforijin Olohun ti o nbe fun won, ti a ko si gbodo jakan kuro nibi ike Olohun ati aforijin Re fun won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" قُلْ لِلَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ يَنْتَهُوا يُغْفَرْ لَهُمْ مَا قَدْ سَلَفَ وَإِنْ يَعُودُوا فَقَدْ مَضَتْ سُنَّتُ الْأَوَّلِينَ" الأنفال 38
'' So fun awon alaigbagbo pe ti won ba siwo, A o darijin won nipa oun ti won ti se rekoja, ti won ba si pada, dajudaju apere oun ti o ba awon ara isiwaju ti rekoja '' Q8:38.
20- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo pelu awon ti kii se musulumi tun ni pe, o se inife daradara fun awon eniyan ni ami igbagbo ododo, eleyi si ri bee nitoripe esin Islam je esin alafia ati ife. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" يا أَبَا هُرَيْرَةَ كُنْ وَرِعًا تَكُنْ أَعْبَدَ الناس وَكُنْ قَنِعًا تَكُنْ أَشْكَرَ الناس وَأَحِبَّ لِلنَّاسِ ما تُحِبُّ لِنَفْسِكَ تَكُنْ مُؤْمِنًا وَأَحْسِنْ جِوَارَ من جَاوَرَكَ تَكُنْ مُسْلِمًا وَأَقِلَّ الضَّحِكَ فإن كَثْرَةَ الضَّحِكِ تُمِيتُ الْقَلْبَ" (صحيح ) صحيح الجامع 4580.
'' ire Abu Hurayra, je alasaje eniyan ki o le ba je olujosin ti o gaju ninu awon eniyan. Je onitelorun eniyan, ki o le je oludupe (eniti o mo oore) julo ninu awon eniyan. Je eni ti yoo ma fe fun awon eniyan oun ti o fe fun emi ara re, ki o le je onigbagbo ododo. Ma se daadaa si awon alabagbe re, ki o le je olugbafa (musulumi) ni ododo. Je ki erin re mo niba, nitoripe opo erin ma npa emi ni '' (At-tirmidhi).


IRORUN ESIN ISLAM NI ABALA IJOSIN
 Dajudaju gbogbo ijosin ti o wa ninu esin Islam, yala eyi ti o je oranyan ni tabi eyi ti o je asegbore, ni o duro lori ipile irorun ati irora ni ibamu si oun ti Olohun sa lesa fun esin Islam. Eleyi ri bee lati le je ki enikookan ninu awon musulumi ni ikapani lati se ijosin ni ona ti yoo gba ma ri adun ijosin naa, ti yoo si fi ni anfaani lati pe Olohun pelu ifokanbale ati idunnu ti yoo ri lori ima se ijosin fun Olohun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe     
" الَّذِينَ آمَنُوا وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُمْ بِذِكْرِ اللَّهِ أَلَا بِذِكْرِ اللَّهِ تَطْمَئِنُّ الْقُلُوبُ (28) " الرعد 28
'' Awon ti won gbagbo ti okan won si bale si iranti Olohun, teti ki o gbo, pelu iranti Olohun ni awon okan fi nbale ''Q13:28.
Awon ijosin wonyi ko ju agbara omoniyan lo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
 « عليكم بما تطيقون فإن الله لا يمل حتى تملوا » البخاري
'' o dowo yin pelu pe ki e se oun ti e ni agbara re, nitoripe dajudaju ko ni su Olohun titi ti yoo fi su yin '' (Al Bukhari).
-- Ninu irorun esin Islam ni wipe gbogbo awon ase ati awon ijosin ti o fi lele ni o wa ni ibamu si adamo ati ikapani omoniyan eyi ti ko si ju agbara won lo, ti ko si tako adamo won. Esin Islam ko fi aaye sile fun musulumi lati se ju agbara re lo, koda bi o se ninu ijosin. Anas (Olohun ki o yonu si) sope:
" أن النبي صلى الله عليه وسلم رأى شيخاً يتهادى بين ابنيه فقال: "ما بال هذا "؟. قالوا: نذر أن يمشي فقال صلى الله عليه وسلم:" إن الله عن تعذيب هذا نفسه لغني ". وأمره أن يركب. رواه البخاري.
'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ri baba arugbo kan ti o nrin tage-tage ni aarin awon omo re meji, ni eni ti o fara ti awon mejeeji, o si beere bayi pe: ki lo se e? won si dahun wipe; o se ileri (fun Olohun) pe oun yoo rin, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe: Olohun roro tayo ifiyaje ti eleyi nse fun emi ara re lo ''. O si pa a lase pe ki o gun nkan igun. (Al Bukhari).
-- Ninu irorun esin Islam ni abala ijosin ni pe Olohun ti O mo toni-toni ti ola Re si ga, yoo ma se akosile esan ise rere sile fun musulumi ni awon asiko ti ko ni anfaani lati se awon ise rere ti o ma nse tele, gege bi asiko ti o nse aisan tabi ti o ba rin irinajo. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" إذا مَرِضَ الْعَبْدُ أو سَافَرَ كُتِبَ له مِثْلُ ما كان يَعْمَلُ مُقِيمًا صَحِيحًا " البخارى
'' nigba ti olujosin fun Olohun ba nse aisan tabi se irinajo, won yoo maa ko (esan daadaa) sile fun gegebi igba ti o wa nile ti o si ni alaafia '' (Al Bukhari).
Esin Islam se irorun pupo ni abala ijosin debi wipe o se awon ede orisirisi ti musulumi le gba esan ni odo Olohun lori re, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" إن الله يحب إن تؤتى رخصه كما يحب إن تؤتى عزائمه "
'' Olohun feran ki a se awon oun ti O se ede (fun wa) lori re, gege bi O se feran ki a se awon oun ti O se ni oranyan '' (At-tirmidhi).
-- Ninu irorun esin Islam ni abala ijosin tun ni pe, gbogbo awon ase, ijosin tabi origun ni o ma ndinku tabi ki won gbe kuro patapata nigba ti eniyan ba wa ni awon ipo kan:
1 – Irorun Esin Islam ni Abala Imora
 Imora je oranyan fun opolopo awon ise ijosin ninu esin Islam. Ti o si jepe omi je oun pataki ti musulumi ni bukata si lati fi se imora, yala fun awon irun wakati marun ojumo ni tabi fun awon irun akigbore (nafila) miran, tabi lati fi we iwe jenaba tabi awon iwe miran ti esin fi lele, gegebi iwe ojo Jimoh tabi iwe awon ojo odun ileya ati itunu awe. Inira ti o le waye latara ai ri omi le ko musulumi sinu wahala ti o si le se okunfa ki okan kole nibi ijosin ki a ma tii so imora funra re. Ninu awon apere irorun esin Islam ni abala imora:
1- Ninu irorun esin Islam ni abala imora ni pe, o gba pe omi je oun ti o mo ni ipile re, niwonba igba ti awo, oorun tabi itowo re ko ba ti yi pada, lati ma je ki erusin Olohun ko sinu inira tabi ifun-pinpin. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" إن الماء لا ينجسه شيء "
'' Dajudaju omi je oun ti o mo, ti ko si oun ti o le ko egbin ba '' (ayafi oun ti o bayi awo, oorun tabi itowo re pada)
2- Ninu irorun esin Islam ni abala imora ni pe o se amuku eranko ti ko legbin (ti o mo) ni oun ti o mo ti o si leto ki a mu fun musulumi tabi lati fi se imora. Kabshah omo Ka'b omo Maalik ti o je iyawo omo Abi Qatadah sope Abu Qatadah wole wa ba oun ni ojo kan, oun si bu omi fun un lati fi se aluwala, ologbo kan si wa lati mu ninu omi naa, bayi ni o te igba omi si odo re ti o si fi mu ninu re. Kabsha wa so bayi pe: o ri mi pe mo n wo oun, o wa so bayi pe: o ya o lenu ire omo mi? mo si dahun wipe beeni. O wa so bayi pe: dajudaju Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إنها ليست بنجس إنهما من الطوافين عليكم والطوافات " صحيح أبي داود
'' won ki i se egbin, sugbon won je alabagbe yin lako ati labo '' (Abu Dawud).
3- Ninu irorun esin Islam ni abala imora ni pe, nigba ti ko ba si omi tabi eniyan ko agara lati lo omi latara aisi omi tabi aisan tabi oju-ogbe ti ko rorun lati bu omi si, tabi ipaya otutu tabi nigba ti omi ti o wa ko ju oun ti a le mu lo, tabi awon nkan miran ti o le so sise aluwala oni yerupe di eto. Sise aluwala oni yerupe ni eto je sise ede ati irorun lati odo Olohun ti o si je pasiparo fun lilo omi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"وَإِنْ كُنْتُمْ مَرْضَى أَوْ عَلَى سَفَرٍ أَوْ جَاءَ أَحَدٌ مِنْكُمْ مِنَ الْغَائِطِ أَوْ لَامَسْتُمُ النِّسَاءَ فَلَمْ تَجِدُوا مَاءً فَتَيَمَّمُوا صَعِيدًا طَيِّبًا فَامْسَحُوا بِوُجُوهِكُمْ وَأَيْدِيكُمْ مِنْهُ مَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيَجْعَلَ عَلَيْكُمْ مِنْ حَرَجٍ وَلَكِنْ يُرِيدُ لِيُطَهِّرَكُمْ وَلِيُتِمَّ نِعْمَتَهُ عَلَيْكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ "
'' Ti eyin ba je alaisan tabi e wa lori irin ajo tabi okan ninu yin de lati ibi igbe tabi e sunmo awon obinrin ti e ko si ri omi, nigbanaa e se aluwala oni yerupe ti o mo, e fi pa awon oju yin ati awon owo yin ninu re. Olohun ko lati se inira fun yin ninu esin. Sugbon Olohun fe lati fo yin mo ati ki o le se asepe idera Re fun yin ki e le ma dupe '' Q5:6.
4- Ninu awon irorun esin Islam ni abala imora tun ni pe, o se pipa bata alamutan (pelu mojemu), lawani ati awon oun ti a fi bo oju ogbe tabi egbo ni eto lai ni yo tabi bo won kuro. Ki musulumi ma ba kan inira latara bibo awon nkan wonyi pataki julo ni asiko otutu. Ja'far omo A'mru omo Umayyah Ad-Damriyyi (Olohun ki o yonu si) gba wa lati odo baba re pe oun ri Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba):
" توضأ ومسح على خفيه وعلى عمامته " مسلم وأبو داود
'' ti o se aluwala ti o si fowo pa bata alamutan ati lawani re " (Muslim ati Abu Dawud).
 Esin islam ko fi ojuure wo ifunlemo, ile-koko ati aise ede fun awon eniyan ninu esin, Jaabir (Olohun ki o yonu si) so bayi pe:
" خَرَجْنَا في سَفَرٍ فَأَصَابَ رَجُلًا مِنَّا حَجَرٌ فَشَجَّهُ في رَأْسِهِ ثُمَّ احْتَلَمَ فَسَأَلَ أَصْحَابَهُ فقال: هل تَجِدُونَ لي رُخْصَةً في التَّيَمُّمِ ؟، فَقَالُوا: ما نَجِدُ لك رُخْصَةً وَأَنْتَ تَقْدِرُ على الْمَاءِ!!! فَاغْتَسَلَ فَمَاتَ فلما قَدِمْنَا على النبي صلى الله عليه وسلم أُخْبِرَ بِذَلِكَ فقال:" قَتَلُوهُ قَتَلَهُمْ الله ألا سَأَلُوا إِذْ لم يَعْلَمُوا فَإِنَّمَا شِفَاءُ الْعِيِّ السُّؤَالُ إنما كان يَكْفِيهِ أَنْ يَتَيَمَّمَ وَيَعْصِرَ أو يَعْصِبَ على جُرْحِهِ خِرْقَةً ثُمَّ يَمْسَحَ عليها وَيَغْسِلَ سَائِرَ جَسَدِه"ِ رواه أبو داود وهو فيصَحِيح الْجَامِع: 4363
'' a se irin ajo lo, okuta kan si rebo lu arakunrin kan ninu wa, o si da ogbe si ori re. O sun o si la ala pe oun ba obinrin ni asepo loju orun, o si se ibeere lodo awon eniyan ti won wa pelu re pe se oun ni eto lati se aluwala oni yerupe? Won si da lohun pe rara ko ni eto!!! bayi ni o fi omi we ti o si jade laye. Nigba ti a de odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) a fun labo oun ti o sele, o si dahun wipe " awon ni won seku pa a, Olohun yoo si fi iya re je won, kilode ti won ko beere nigba ti won ko nimo nipa re, nigba ti o si je pe ibeere ni oogun aimokan, o ti to fun ki o kan se aluwala oni yerupe ki o si fi ekisa we oju ogbe re leyin naa ki o si fi owo paa, ki o si we awon orike-rike ara ti o ku '' (Abu Dawud ati At-tirmidhi).
5- Ninu irorun esin Islam ni abala imora ni pe, o se ile ni oun ti o mo ni ipile re, ki musulumi le ni anfaani lati se ijosin re ni eyikeyi aaye ti o ba fe (ayafi ni saare (ite oku) tabi ile iwe) niwonba igba ti egbin ko ba fojuhan ni aaye naa. Esin Islam ko se irun kiki ni eto ni awon aaye adayanri nikan gegebi ile ijosin, ki musulumi ma ba ko sinu inira ati wahala ni asiko ti o ba fe se ijosin. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" وَجُعِلَتْ لِيَ الْأَرْضُ طَيِّبَةً طَهُورًا وَمَسْجِدًا فَأَيُّمَا رَجُلٍ أَدْرَكَتْهُ الصَّلَاةُ صلى حَيْثُ كان "متفق عليه
'' won (Olohun) se ile fun mi ni oun ti o dara ti o mo ti o si je aaye ijosin, eyikeyi (omo ijo mi) ti irun ba to ba ni eyikeyi aaye ni o ni eto lati ki irun ni aaye naa '' (Al Bukari ati Muslim).
6- Ninu irorun esin Islam ni abala imora tun ni pe, mimu egbin kuro lori ile nigba ti egbin ba wa nibe, ti ko si mu wahala tabi inira dani rara. Apejuwe eleyi ni oro arakunrin larubawa oko kan ti o to sinu mosalasi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti awon eniyan si fe fiya jee, sugbon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun won pe:
" دَعُوهُ (اتركوه) وَهَرِيقُوا على بَوْلِهِ سَجْلًا من مَاءٍ أو ذَنُوبًا من مَاءٍ فَإِنَّمَا بُعِثْتُمْ مُيَسِّرِينَ ولم تُبْعَثُوا مُعَسِّرِينَ" البخاري
'' e fi sile, ki e si da odiwon ifami kekere omi kan tabi ninla si ito re, nitoripe won (Olohun) gbeyin dide ni oluse idera (fun awon eniyan), won ko si gbeyin dide ni olufi- inira kan won on " (Al Bukhari).
7- Ninu irorun esin Islam ni abala imora tun ni pe, o se ito, igbe ati eje (niwonba igba ti kii ba se eje ti nsan tabi ti o po) awon eran ti jije won je eto, ni oun ti o mo ti ko si le ko egbin ba aso tabi aaye ti o ba da si ayafi ile rakunmi nikansoso. Jaabir omo samra (Olohun ki o yonu si) sope:
 " أَنَّ رَجُلًا سَأَلَ رَسُولَ اللَّهِ صلى الله عليه وسلم أَأَتَوَضَّأُ من لُحُومِ الْغَنَمِ ؟ قال:"إن شِئْتَ فَتَوَضَّأْ وَإِنْ شِئْتَ فلا تَوَضَّأْ" قال: أَتَوَضَّأُ من لُحُومِ الْإِبِلِ ؟ قال:"نعم فَتَوَضَّأْ من لُحُومِ الْإِبِلِ" قال: أُصَلِّي في مَرَابِضِ الْغَنَمِ ؟ قال:" نعم " قال: أُصَلِّي في مَبَارِكِ الْإِبِلِ ؟ قال:" لَا " مسلم
'' arakunrin kan bi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wipe se o ye ki oun se aluwala ti oun ba je eran agutan? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe: ti o ba fe se aluwala ti o ba si fe ma se aluwala. O tun beere wipe: se o ye kin se aluwala ti mo ba je eran rakunmi? O si tun da lohun wipe: beeni, se aluwala ti o ba je eran rakunmi. O tun beere wipe: se mo le ki irun ni ile agutan? O dahun wipe: beeni. O tun beere wipe: se mo le ki irun ni ile rakunmi? O si dahun wipe: rara '' (Muslim).
2 – Irorun Esin Islam ni Abala Irun Kiki
 Ninu pataki irun kiki ni pe o je asopo laarin erusin ati Oluwa re. Musulumi yoo pa sofo pelu Oluwa re lori irun, ti yoo si ma pe E ni ohun jeje pelu idirebe si odo Re. Ni gbogbo igba ti musulumi ba ti nteri sinu igbadun aye ti imole igbagbo si njo ajoreyin ninu igbaya re ni oluperun yoo ma pepe fun irun, bayi ni imole igbagbo yoo si tun bere si ni jo geregere ninu igbaya re lakotun, ti yoo si ma be ni asepo pelu adeda re ni gbogbo igba. Eleyi ri bee latara wipe irun wakati marun ojumo ni musulumi yoo ma ki ni jamah (akojopo musulumi) ni masalasi ayafi ti idiwo pataki kan ba sele si. Latara eleyi imore-eni yoo sele laarin won, ife ati ajosepo yoo si ma waye laarin won, ti won yoo si ma se ibeere nipa alamori ara won.
 Eleyi yoo si je okunfa ipare gbogbo oniranran iwa emijuo-iwo-ojumi ti o wa laarin awujo, latara wipe gbogbo won yoo to ni egbeegbe ara won, agbalagba inu won pelu awon omode, olowo ati awon alaini inu won, awon eniyan pataki ninu won pelu awon eniyan yepere, dogbandogba ni onikaluku yoo je ni abala irora eni sile fun Olohun ati nibi iduro siwaju Re ni eni ti o doju ko gabasi (kiblah) kansoso, ti won yoo si ma jo se isesi kannaa.
Irun kiki ni eyi ti o ga julo ninu awon origun esin mararun leyin ijeri pe okansoso ni Olohun atipe Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je erusin ati Ojise Re. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope: Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إن أول ما يحاسب به العبد صلاته فإن صلحت صلاته صلح سائر عمله وإن فسدت صلاته فسد سائر عمله " أخرجه أحمد وابن ماجة
'' dajudaju akoko oun ti won (Olohun) yoo se isiro erusin le lori ni irun re, ti irun re ba ni alafia gbogbo ise re ni yio ni alafia, sugbon ti irun re ko ba dara gbogbo ise re yoku naa ni o ti baje '' (Ahmad ati Ibn Majah).
 Ni iwoye si wipe irun je oun ti o ma nwaye ni igba marun ni ojumo, irorun ati irora ti o so pomo o fojuhan gbangba, nitori ki awon musulumi le ki pelu inu didun ati araya laini si inira nibe rara.
Eleyi ni die ninu awon apejuwe irorun esin Islam ni abala irun kiki:
1- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki ni pe, o je oun ti olujosin yoo ma ki ni ibamu si ikapani ati agbara re. Ninu awon oranyan irun kiki ni ki a duro ki fun eni ti o ba ni agbara lati duro, sugbon ti eniyan ba kagara lati ki irun ni iduro o ni anfaani lati ki ni ijoko, ti ko ba ni agbara lati ki ni ijoko o ni anfaani lati ki ni ifegbelele, ti ko ba tun ni ikapa bee o ni anfaani lati ki pelu nina ika. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" صَلِّ قَائِمًا فَإِنْ لَمْ تَسْتَطِعْ فَقَاعِدًا، فَإِنْ لَمْ تَسْتَطِعْ فَعَلَى جَنْبٍ " البخاري
'' ki irun ni iduro, sugbon ti o ko ba ni ikapa ki ni ijoko, ti o ko ba tun ni ikapa fi egbe lele ki '' (Al Bukhari).
2- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki ni pe, o se ni oun ti a le ki ni awon isesi orisirisi ni ibamu si aaye ti a ba wa yala ni asiko ifayabale ni tabi ni asiko ipaya. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" حَافِظُوا عَلَى الصَّلَوَاتِ وَالصَّلَاةِ الْوُسْطَى وَقُومُوا لِلَّهِ قَانِتِينَ (238) فَإِنْ خِفْتُمْ فَرِجَالًا أَوْ رُكْبَانًا "
'' Ki e ma so awon irun paapaa julo irun ti aarin, ki e si dide duro fun Olohun ninu irun, ki e si te ori yin ba fun Un \\ Sugbon ti e ba nberu (awon ota) ki e ma ki irun yin ni ori irin tabi ni ori rakunmi '' Q2:238-239.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki ni pe, o se didin awon irun olopa merin ku si meji pelu kiki irun meji papo ni asiko irun kan ni etofun onirinajo, yala o ki mejeeji papo ni asiko irun akoko ni tabi o ki won papo ni asiko irun eleekeji ni ibamu si oun ti o ba ro lorun. Ya'la omo Umayyah (Olohun ki o yonu si) sope:
" قلت لِعُمَرَ بن الْخَطَّابِ: " فليس عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَنْ تَقْصُرُوا من الصَّلَاةِ إن خِفْتُمْ أَنْ يَفْتِنَكُمْ الَّذِينَ كَفَرُوا" (سورة النساء آية:101) فَقَدْ أَمِنَ الناس فقال: عَجِبْتُ مِمَّا عَجِبْتَ منه فَسَأَلْتُ رَسُولَ اللَّهِ صلى الله عليه وسلم عن ذلك فقال:" صَدَقَةٌ تَصَدَّقَ الله بها عَلَيْكُمْ فَاقْبَلُوا صَدَقَتَهُ" مسلم
'' mo so fun U'mar omo Khatab (Olohun ki o yonu si) wipe: oro Olohun ti so bayi pe '' ko si ese fun yin pe ki e dinku ninu awon irun yin, bi eyin ba nberu pe awon alaigbagbo yoo yo yin lenu '' (Q4:101), ko si iberu mo bayi awon eniyan ti wa ninu ifokanbale, (ki wa lo tun faa ti a fi ndin irun ku ni irinajo)? O si dahun wipe: bi o se se o ni eemo ni o se se emi naa ti mo si beere lowo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lori re, ti o si dahun wipe '' itore ni lati odo Olohun fun yin, e tewo gba ore Olohun '' (Muslim).
4- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki tun ni pe, o se kiki irun meji papo ni eto fun alaisan, tabi ni asiko ti otutu ti o le ba mu ati nigba ti ojo ti o lagbara ba ro, bakannaa eniti o ni bukata ti o lagbara koda ko ma je onirinajo. Omo A'baas sope:
" صلّى رسول اللَّهِ صلى الله عليه وسلم الظُّهْرَ وَالْعَصْرَ جميعا بِالْمَدِينَةِ في غَيْرِ خَوْفٍ ولا سَفَرٍ، قال أبو الزُّبَيْر:ِ فَسَأَلْتُ سَعِيدًا لِمَ فَعَلَ ذلك ؟ فقال: سَأَلْتُ بن عَبَّاسٍ كما سَأَلْتَنِي ؟ فقال: أَرَادَ أَنْ لَا يُحْرِجَ أَحَدًا من أُمَّتِهِ" مسلم
'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki irun Aila ati Alasari papo ni ilu Modinah laisi iberu tabi irinajo, Abu Zubayr sope:mo bi sa'eed wipe ki lo de ti o se bee? o si dahun wipe: mo bi omo A'baas gegebi o se bi mi yi, o si dahun wipe: ko fe ki inira kan enikankan ninu ijo re '' (Muslim).
5- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki tun ni pe, o se asiko irun ni oun ti o fe ti ko si si ifunlemo ti yoo ko musulumi si inira lori re. jaabir omo Abdullah sope:
" جاء جبرائيل إلى النبي صلى الله عليه وسلم حين مالت الشمس فقال:" قم يا محمد فصلى الظهر حين مالت الشمس ثم مكث حين إذا كان فيء الرجل مثله جاءه للعصر فقال:" قم يا محمد فصلى العصر ثم مكث حتى إذا غابت الشمس جاءه فقال:" قم فصل المغرب فقام فصلاها حين غابت الشمس سواء ثم مكث حتى إذا غاب الشفق جاءه فقال:" قم فصل العشاء فقام فصلاها ثم جاءه حين سطع الفجر بالصبح فقال:" قم يا محمد فصل فقام فصلى الصبح ثم جاءه من الغد حين كان فيء الرجل مثله فقال:" قم يا محمد فصل فصلى الظهر ثم جاء حين كان فيء الرجل مثليه فقال:" قم يا محمد فصلى العصر ثم جاءه للمغرب حين غابت الشمس وقتا واحدا لم يزل عنه فقال:" قم فصل فصلى المغرب ثم جاءه للعشاء حين ذهب ثلث الليل الأول فقال:" قم فصل العشاء ثم جاءه للصبح حين أسفر جدا فقال:" قم فصل الصبح ثم قال:" ما بين هذين وقت كله " النسائي صحيح الترمذي ( 150 )
'' Jubreel wa ba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nigba ti oorun ye-atari, o si so bayi pe: dide ire Muhammad, o si ki irun Aila nigba ti oorun ye atari. O wa bee titi ti o fi dipe ojiji eniyan se deedee iduro re, o si de fun irun Alasari, o si sope: dide ire Muhammad, bayi ni o tun ki irun Alasari. O tun wa bee titi ti o fi di pe oorun wo, o tun de, o si sope: dide ki o ki irun Mongiribi, o dide o si ki irun Mongiribi ni igba ti oorun wo. O tun wa bee titi ti pupa resuresu oju sonmo fi pare, o tun wa ba a, o si so pe: dide ire Muhammad ki o ki irun Ishai, o si dide kii. O tun wa baa nigba ti afemoju bere, o si sope: dide ire Muhammad ki o kirun. O dide o si ki irun Asunbaa. Leyin naa o tun wa ni ojo keji nigba ojiji eniyan se deedee iduro re, o si sope: dide ire Muhammad ki o ki irun, o dide o si ki irun Aila. Leyin o tun de ni igba ti ojiji eniyan se deedee ilopo meji re, o si sope: dide ire Muhammad o si ki irun Alasari. Leyin naa o tu de fun irun Mongiribi ni asiko ti oorun wo, deede asiko ti o wa ni ana, o si sope: dide ki o ki irun, o si ki irun Mongiribi. Leyin naa ni o tun wa fun irun Ishai ni igba ti ida alakoko ti koja ninu idameta oru, o si sope: dide ki o ki irun Ishai. Leyin naa o de fun irun Asunbaa nigba ti oju ojo ti la daradara, o si sope: dide ki o ki irun Asunbaa. Ni igbeyin ni o wa sope: oun ti o nbe ni aarin awon asiko mejeeji yi ni asiko irun kookan '' (An-nasai ati At-tirmidhi).
6- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki ni pe, ti alekun tabi adinku ba sele si musulumi lori irun latara igbagbe tabi asise, ko ni tun irun naa ki ni odidi, bikosepe yoo se iforikanle igbagbe, eleyi je ise ede ati irorun bakannaa o si je ifi imu esu gbole, nitoripe o je eni ti o ma nse ojukokoro lori ki ijosin erusin Olohun di oun ibaje, bakannaa ni o je iyo Olohun ninu. Abu Saee'd Al-Khudriy sope: Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إذا شَكَّ أحدكم في صَلَاتِهِ فلم يَدْرِ كَمْ صلى ثَلَاثًا أَمْ أَرْبَعًا فَلْيَطْرَحْ الشَّكَّ وَلْيَبْنِ على ما اسْتَيْقَنَ ثُمَّ يَسْجُدُ سَجْدَتَيْنِ قبل أَنْ يُسَلِّمَ فَإِنْ كان صلى خَمْسًا شَفَعْنَ له صَلَاتَهُ وَإِنْ كان صلى إِتْمَامًا لِأَرْبَعٍ كَانَتَا تَرْغِيمًا لِلشَّيْطَانِ" رواه مسلم
'' ti enikan ninu yin ba nse iyemeji lori irun re, ti ko mo iye ti o ti ki yala meta ni tabi merin, ki o yara gbe iyemeji si egbe ki o si duro lori eyi ti o da loju, leyin naa ki o wa forikanle ni eemeji siwaju ki o to salamo, ti o ba jepe marun ni o ki ni igbeyin, eleyi yoo je isipe fun un, ti o ba si jepe merin naa ni, yoo je fifi imu esu gbole '' (Muslim).
7- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki tun ni pe, nigba ti musulumi ba se alaimo adojuko gabasi (kiblah) tabi ko ri oun ti yoo se atona re lori re, nigbanaa o ni anfaani lati lo lakaye re lati moo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلِلَّهِ الْمَشْرِقُ وَالْمَغْرِبُ فَأَيْنَمَا تُوَلُّوا فَثَمَّ وَجْهُ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ وَاسِعٌ عَلِيمٌ" البقرة 115
'' Ti Olohun ni ibuyo oorun ati ibuwo re, nitorinaa ibikibi ti e ba da oju yin ko ibe naa ni adojuko Olohun. Dajudaju Olohun ni Olugbaaye Onimimo '' Q2:115.
8- Ninu irorun esin Islam ni abala irun kiki ni pe, o ko fun imam pe ki o ki irun ti o gun ju ni askoo ti o ba nki irun fun janma. Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) sope Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إذا صلى أحدكم لِلنَّاسِ فَلْيُخَفِّفْ فإن منهم الضَّعِيفَ وَالسَّقِيمَ وَالْكَبِيرَ وإذا صلى أحدكم لِنَفْسِهِ فَلْيُطَوِّلْ ما شَاءَ " البخاري
'' nigba ti enikookan yin ba nki irun fun awon eniyan ko ya se ni fufuye nitoripe ole nbe ninu won pelu alaisan ati agbalagba, sugbon nigba ti enikookan yin ba nkirun fun ra re ki o faa gun bi o ba ti fe '' (Al Bukhari).
3 – Irorun Esin Islam ni Abala Zaka Yiyo
Ninu pataki saka yiyo ni pe won (Olohun) se ni ilana lati pa osi re ni awujo elesin Islam, bakannaa lati wa ojutu si awon aburu ti o le waye latari osi gegebi ole jija, ipaniyan ati ifisuta kan dukia awon eniyan. Bakanna ni o tun je itaji fun emi ajosepo awujo laarin awon musulumi, pelu gbigbo bukata awon alaini ati talaka, ki won si le ro won loro kuro nibi iyepere ti o le waye latara ima toro.
Eleyi ni die ninu awon apejuwe irorun esin Islam ni abala yiyo zaka:
 1- Ninu irorun esin Islam ni abala yiyo zaka ni pe, o je oun ti a ma nyo ninu awon dukia ti ko ga ju ara lo, kii si se oun ti a ma nyo ninu awon ojulowo ati eyi to dara julo ninu dukia, ninu oro ti Muadh (Olohun ki o yonu si) gba wa ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti sope:
" إياك وكرائم أموالهم ". رواه البخاري
'' sora, ma se gba eyi ti o je ojulowo dukia won '' (Al Bukhari).
2- Ninu irorun esin Islam ni abala yiyo saka ni pe, odiwon ti o je oranyan lati yo ninu dukia je oun ti o kere pupo ni ibamu si iye ti o je oranyan ti a gbodo ni lowo ki a to le yo zaka. Bakannaa tun ni pe saka ko ni je oranyan lori dukia ayafi leyin igba ti odun kan geerege ti elesin Islam ba lo lori re. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" ليس عليك شيء حتى يكون لك عشرون ديناراً فإذا كانت لك عشرون ديناراً وحال عليها الحول ففيها نصف دينار فما زاد فبحساب ذلك وليس في مال زكاة حتى يحول عليه الحول " أحمد صحيح. رواه أبو داود
'' nkankan (zaka) ko je oranyan le o lori ayafi nigba ti o ba to ni ogun Dinari, to odun kan si koja lori re, nigbanaa ni o wa yo idaji Dinari ninu re, bi o ba se wa lekun naa ni o se ma yoo. Zaka yiyo kii se oranyan lori dukia titi ti odun kan yoo fi koja lori re '' (Ahmad ati Abu Dawud).
3- Ninu irorun esin Islam ni abala zaka yiyo ni abala awon ogbin ni pe, a gbodo woye si ona ti a gba toju re (fi omi si) ki a le mo iru odiwon wo ni a o yo ninu re, nitoripe idakan ninu idamewa ni o je oranyan lori eyi ti o ba jepe ojo ni o ro si, nigbati idakan ninu ida ogun si je oranyan lori eyi ti a ba bu omi rin. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so ninu oro re wipe:
 « فيما سقت السماء والعيون أو كان عثريا العشر وما سقي بالنضح نصف العشر » رَوَاهُ اَلْبُخَارِيّ
'' eyikeyi ti o ba hu latara ojo, seleru tabi ti o nfa omi lati inu ile, idakan ninu ida mewa (ni oranyan zaka nibe), sugbon eyi ti a ba bu omi rin, idakan ninu ida ogun (ni oranyan zaka nibe) '' (Al Bukhari).
4- Ninu irorun esin Islam ni abala zaka yiyo tun ni pe, ko je oranyan lori eni ti ko ni ikapa yala latara osi ni tabi lati ara ikagara latari awon ojuse oranyan ti o wa lorun re gegebi gbese tabi oun ti o joo. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba):
" لاصدقة إلا عن ظهر غنى " أحمد
'' ore (zaka yiyo) kii se oranyan fun eni ti ko ni '' (Ahmad).
Oro ko mo lori eleyi nikan, biko sepe irun eni bayi tun je eni ti o leto si gbigba zaka nitoripe o ti wa ninu awon ti o leto si. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاءِ وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ" التوبة 60
'' Ore (zaka) wa fun awon talika ati awon alaini ati awon ti nsise re ati awon ti a nfa okan won (si inu Islam) ati fun irapada awon eru ati awon ti o je gbese ati si oju ona Olohun ati omo oju ona, oranyan ni lati odo Olohun, Olohun mi Olumo Ologbon '' Q9:60.
5- Ninu irorun esin Islam ni abala saka yiyo tun ni pe, o sezsaka yiyo ni ona ola fun eni ti nyoo ti yoo si kuro ni gbese lorun re, eleyi ti yoo si je okunfa fun ki o maa yoo ni kiakia pelu idunnu ati ayo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"خُذْ مِنْ أَمْوَالِهِمْ صَدَقَةً تُطَهِّرُهُمْ وَتُزَكِّيهِمْ بِهَا وَصَلِّ عَلَيْهِمْ إِنَّ صَلَاتَكَ سَكَنٌ لَهُمْ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ" التوبة 103
'' Gba itore anu (zaka) ninu oro won, ki o fi fo won mo ati ki o fi so won di mimo, ki o si se adua fun won. Dajudaju adua re ifokanbale ni o je fun won. Olohun si Olugboro Onimimo '' Q9:103.
4 -- Irorun Esin Islam ni Abala Awe Gbigba
Ninu pataki awe gbigba ni pe, won se ni ilana ki musulumi le ni igbonmo nipa inira ti nkan awon omo iya re ti won je alaini ti won si ni bukata lati gbo. Eleyi yoo je ki o mojuto awon iwo won ki o si ma se iwadi nipa ipo ti won wa lati gbo bukata won ati lati ma se aanu fun won. Bakanaa ni o tun je ija emi ara eni logun lori awon ifekufe re ati awon yodoyindin aye, eleyi ti yoo je ki musulumi jinna si awon oro koro ati ise aburu.
Eleyi si ni die ninu awon irorun esin Islam ni abala awe gbigba:
1- Ninu irorun esin Islam ni abala awe gbigba ni pe, ko je oranyan ju osu kan pere lo ninu odun, osu naa si ni osu Ramadan. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" شَهْرُ رَمَضَانَ الَّذِي أُنْزِلَ فِيهِ الْقُرْآنُ هُدًى لِلنَّاسِ وَبَيِّنَاتٍ مِنَ الْهُدَى وَالْفُرْقَانِ فَمَنْ شَهِدَ مِنْكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ وَمَنْ كَانَ مَرِيضًا أَوْ عَلَى سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِنْ أَيَّامٍ أُخَرَ يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ وَلِتُكْمِلُوا الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُوا اللَّهَ عَلَى مَا هَدَاكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ" البقرة 185
'' Osu Ramadan eyi ti won (Olohun) so Al-kurani kale ninu re, ilana ni o je fun awon eniyan ati eri ododo ti ilana-otito naa ati ipinya (ododo pelu iro); nitorinaa enikeni ti osu naa ba se oju re ninu yin, ki o yaa gba awe naa, eni ti o ba nse aisan tabi ti o nbe ni ori irinajo (yoo san awe naa pada ninu) onka awon ojo miran. Olohun nfe irorun pelu yin ko si fe inira fun yin, ki e si se asepe onka naa, ki e ba le se agbega fun (oruko) Olohun nitori ona ti o fi mo yin ati ki eyin le ma se ope '' Q2:185.
2- Ninu irorun esin Islam ni abala awe gbigba tun ni pe, o se ni oun ti o ni asiko kan gbogi latara ki musulumi ma ba wa ninu iyonu lori mimo ibere ati ipari re lojoojumo. ko leto ki a se alekun tabi adinku nibe. O bere lati igba ti ojumo ba ti mo (ti alifajari ba yo) titi ti oorun yoo fi wo. Olohun ti ola Re so bayi pe:
" أُحِلَّ لَكُمْ لَيْلَةَ الصِّيَامِ الرَّفَثُ إِلَى نِسَائِكُمْ هُنَّ لِبَاسٌ لَكُمْ وَأَنْتُمْ لِبَاسٌ لَهُنَّ عَلِمَ اللَّهُ أَنَّكُمْ كُنْتُمْ تَخْتَانُونَ أَنْفُسَكُمْ فَتَابَ عَلَيْكُمْ وَعَفَا عَنْكُمْ فَالْآنَ بَاشِرُوهُنَّ وَابْتَغُوا مَا كَتَبَ اللَّهُ لَكُمْ وَكُلُوا وَاشْرَبُوا حَتَّى يَتَبَيَّنَ لَكُمُ الْخَيْطُ الْأَبْيَضُ مِنَ الْخَيْطِ الْأَسْوَدِ مِنَ الْفَجْرِ ثُمَّ أَتِمُّوا الصِّيَامَ إِلَى اللَّيْلِ وَلَا تُبَاشِرُوهُنَّ وَأَنْتُمْ عَاكِفُونَ فِي الْمَسَاجِدِ تِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ فَلَا تَقْرَبُوهَا كَذَلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ آيَاتِهِ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ (187) " البقرة
'' A se oru awe ni eto fun yin lati sunmo awon aya yin, aso ni won je fun yin eyin naa si je aso fun won, Olohun mo pe e se abosi emi ara yin, sugbon O siju aanu wo yin, O si se imojukuro fun yin, nitorinaa ni isinsinyi e sunmo won, ki e si wa (lati se) oun ti Olohun pa lase fun yin, ki e maa je, ki e si maa mu titi iyato owu funfun si owu dudu yoo fi han fun yin ni afemoju owuro, leyin naa ki e se asepe awe naa titi di ale, e ko si gbodo sunmo won ni igba ti e nse atipo sinu mosalasi, iwonyi ni enu-aala (ofin) Olohun nitorinaa e ma se sunmo-o, bayi ni Olohun se alaye awon aaya (amin) Re fun awon eniyan ki won ba le beru (Olohun) Q2:187.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala awe gbigba tun ni pe, o ko funni lati gba awe agbayipo latara inira ti o wa nibe atipe o je ise ni oranyan fun emi oun ti Olohun ko se ni ilana. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" لا وصال في الصيام "ابن حبان "الصحيحة" (2894).
'' awe agbayipo ko si ninu awe '' (Ibn Hiban).
4- Ninu irorun esin Islam ni abala awe gbigba tun ni pe, o se esan re ni oun ti tobi pupo ti ko si ni odiwon rara. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" قال الله:" كُلُّ عَمَلِ بن آدَمَ له إلا الصِّيَامَ فإنه لي وأنا أَجْزِي بِهِ وَالصِّيَامُ جُنَّةٌ وإذا كان يَوْمُ صَوْمِ أَحَدِكُمْ فلا يَرْفُثْ ولا يَصْخَبْ فَإِنْ سَابَّهُ أَحَدٌ أو قَاتَلَهُ فَلْيَقُلْ إني امْرُؤٌ صَائِمٌ وَالَّذِي نَفْسُ مُحَمَّدٍ بيده لَخُلُوفُ فَمِ الصَّائِمِ أَطْيَبُ عِنْدَ اللَّهِ من رِيحِ الْمِسْكِ لِلصَّائِمِ فَرْحَتَانِ يَفْرَحُهُمَا إذا أَفْطَرَ فَرِحَ وإذا لَقِيَ رَبَّهُ فَرِحَ بِصَوْمِهِ " متفق عليه
'' Olohun so pe: gbogbo ise omo Aadamo ni o je ti e, ayafi awe nikan nitoripe o je temi emi naa ni ma si san esan re, awe gbigba je odi-iso, nigba ti enikookan yin ba ngba awe ko gbodo so isokuso, ko gbodo maa pariwo tabi gbe ohun soke, ti enikeni ba bu tabi o (fe) ba wo ijakadi, ki o so (fun) wipe; emi je alaawe. Mo fi eni ti emi Muhammad nbe lowo re bura pe oorun enu alaawe dara ni odo Olohun ju oorun turari Alimisiki lo, idunnu meji ni o nbe fun alaawe ti yoo ma dunnu pelu re; nigba ti o ba nsinu yoo dunnu ati nigba ti o ba pade Oluwa re yoo dunnu pelu awe re (Al Bukari ati Muslim).
5- Ninu irorun esin Islam ni abala awe gbigba tun ni pe, o se ede fun alaisan ati arinrin ajo pe ki won fi awe sile ti o ba mu inira lowo fun won, ki won si san pada nigba ti won ba ni ikapa re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"... فَمَنْ شَهِدَ مِنْكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ وَمَنْ كَانَ مَرِيضًا أَوْ عَلَى سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِنْ أَيَّامٍ أُخَرَ يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ وَلِتُكْمِلُوا الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُوا اللَّهَ عَلَى مَا هَدَاكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ" البقرة 185
'' ….. nitorinaa enikeni ti osu naa ba se oju re ninu yin, ki o yaa gba awe naa, eni ti o ba nse aisan tabi ti o nbe ni ori irinajo (yoo san awe naa pada ninu) onka awon ojo miran. Olohun nfe irorun pelu yin ko si fe inira fun yin, ki e si se asepe onka naa, ki e ba le se agbega fun (oruko) Olohun nitori ona ti O fi mo yin ati ki eyin le maa se ope '' Q2:185.
Olohun ati Ojise Re (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti se ni eewo pe ki eniyan la bo ara re lorun oun ti ko ni agbara re koda ki o je lori ijosin. Jaabir omo Abdullah (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) sope:
" كان رسول اللَّهِ صلى الله عليه و سلم في سَفَرٍ فَرَأَى رَجُلًا قد اجْتَمَعَ الناس عليه وقد ظُلِّلَ عليه فقال:" ماله ؟" قالوا: رَجُلٌ صَائِمٌ فقال رسول اللَّهِ صلى الله عليه وسلم:"ليس من الْبِرِّ أَنْ تَصُومُوا في السَّفَرِ" صحيح - "الإرواء" (4/ 59). وفي لفظ لمسلم:"عَلَيْكُمْ بِرُخْصَةِ اللَّهِ الذي رَخَّصَ لَكُمْ" أخرخه مسلم
'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa ni irinajo kan bayi ni o ri arakunrin kan ti awon eniyan pejo le lori ti ojiji si da boo, bayi o si sope: ki lo sele si? won si dalohun wipe: alaawe ni, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe: kii se ninu ise daadaa ni ki e maa gba awe ni ori irinajo. Ninu egbawa miran o sope: ede ti Olohun se fun yin di owo yin '' (Muslim).
6- bakannaa ninu irorun esin Islam ni abala awe gbigba tun ni pe, o se ede fun obinrin ti nfun omo loyan ati oloyun pe ki won fi awe sile ti won ba npaya lori ara won tabi lori omo won, ki won si san an pada nigba ti o ba ro won lorun, bakan naa ni agbalagba ti ojo-ori re ko gbaa laaye lati gba awe ti yoo si san an pelu bibo alaini. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا " (البقرة 286)
'' Olohun ko gbe oun ti o ju enikankan le l'ori bikosepe bi agbara re ti mo'' Q2:186.
7- Ninu irorun esin Islam ni abala awe gbigba tun ni pe, o ka fun enikeni ti o ba gbagbe ti o fi jeun tabi mu omi tabi won fi tipatipa mu ja awe re si eni ti awe re `ni alaafia ti awe ko si ja rara. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" من نسي وهو صائم فأكل أو شرب فليتم صومه فإنما الله أطعمه وسقاه" مُتَّفَقٌ عَلَيْهِ.
'' enikeni ti o ba gbagbe, ti o si je alaawe sugbon, ti o wa jeun tabi mu omi, ki o ya maa ba awe re lo, nitoripe Olohun ni O fun ni jije ati mimu '' (Al Bukari ati Muslim).
5 -- Irorun Esin Islam Ni Abala Hajji Sise
 Ninu awon afojusun ti o ga julo fun ise Hajji ni sise Olohun ni okansoso ati fifi iranti Re lele, nigba ti o si jepe amin re ti won yoo maa pe-ni-apetunpe naa ni '' mo nje ipe Re iwo Olohun mo nje ipe Re, mo nje ipe Re ko si orogun fun O mo nje ipe Re, dajudaju gbogbo ope ati idera ti Re nikan ni ati ola ko si orogun fun O '' eyi ti o tumo si pe '' ire Olohun a wa si aaye ni eni ti ntele ase Re, ati ni eni ti nrankan iyonu Re, ati ni eni ti nse ifirinle ije okansoso Re atipe dajudaju iwo nikan ni O leto si ijosin yato si elomiran ''.
 Ko si opinya laarin alaponle ati eni yepere ninu won, tabi laarin eniyan dudu ati eniyan funfun, tabi laarin larubawa ati eni ti kii se larubawa, dogbandogba ni onikaluku ni iwaju Olohun, ko si iyato laarin won ayafi ni abala iberu Olohun. Eleyi nse ifirinle ije omo-iya laarin awon musulumi ati ise igbonmo ati afokante won ni okansoso.
 Die ninu awon irorun ati irora esin Islam ni abala Hajji sise:
1- Ninu irorun esin Islam ni abala Hajji sise ni pe, ko se ni oranyan ju eekan lo ninu igbesi aye, nitoripe ti o ba je ijosin odoodun yoo mu inira ti o po lowo. Eleyi si ntoka lori ije ododo ise ti anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba) mu wa, nitoripe ti o ba je oranyan odoodun ni, ilu Makkah ko ba ti le gba onka repete gbogbo musulumi ni asiko kan naa. Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) sope:
" خطبنا رسول الله صلى الله عليه وسلم فقال:" أيها الناس قد فرض الله عليكم الحج فحجوا " فقال رجل: أكلَّ عام يا رسول الله؟ فسكت حتى قالها ثلاثا، فقال رسول الله صلى الله عليه وسلم:" لو قلت نعم لوجبت ولما استطعتم"، ثم قال: ذروني ما تركتكم فإنما هلك من كان قبلكم بكثرة سؤالهم واختلافهم على أنبيائهم، فإذا أمرتكم بشيء فأتوا منه ما استطعتم وإذا نهيتكم عن شيء فدعوه » رواه مسلم.
'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba wa soro o si so bayi pe: eyin eniyan Olohun ti se Hajji sise ni oranyan fun yin, ki e ya see '' arakunrin kan si dahun wipe: se gbogbo odoodun ni bi ire ojise olohun? O dake titi ti o fi beere ni eemeta, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa dahun wipe: '' ti mo ba fi sope beeni ko ba di oranyan e ko si ni lagbara re '' leyin naa ni o so pe: e fi mi sile lori oun ti mi o ba so fun yin, nitoripe oun ti o se okunfa iparun awon ti o siwaju yin ni pe, won maa nbeere ibeere ti o poju, won si maa nyapa awon Anabi won (ike ati ola Olohun ki o ma ba won), nitori naa ti mo ba pa yin ni ase nkankan e se bi e ba se ni agbara mo, sugbon ti mo ba ko nkankan fun yin e ya jinna si patapata '' (Muslim).
2- Ninu irorun esin Islam ni abala Hajji sise tun ni pe, o ma nkuro ni oranyan fun eni ti ko ni ikapani yala ti owo tabi ti ara lati se ise Hajji (pelu pe o je okan ninu awon origun esin Islam), gegebi alaisan lailai ti aisan re ko fun ni anfaani lati se ise Hajji sugbon ti o si ni owo re, yoo ran elomiran lati ba se e, bakan naa ni talika ti ko ni owo ti o le gbo ju bukata re ati awon ara-ile re lo, ise Hajji yoo kuro ni oranyan fun un ni asiko yi. Nitoripe Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلِلَّهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ الْبَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلًا وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ الْعَالَمِينَ (97) "
'' …. Irin-ajo lo si Ile naa nitori ti Olohun je iwo (orayan) fun gbogbo eniyan enikeni ti o ba ni agbara irin-ajo lo si ibe, enikeni ti o ba si se aigbagbo, dajudaju Olohun ti ro oro ju gbogbo eda lo '' Q3:97.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala Hajji sise tun ni pe, o se ni oun ti o gbaaye fun musulumi lati se esa eyi ti o ba wu ninu awon iran meteta ti Hajji pin si (Hajji aladase, Hajji ati Umura alasepo, ati Hajji leyin umura) ni ibamu si asiko re ati owo re.
4- Ninu irorun esin Islam ni abala Hajji tun ni pe, o gbe awon ona abayo (itanran) kale nigba ti eniyan ba se nkankan ninu awon oun ti ko leto ki alalaji se ni eyi ti o le ko aaye tabi adinku ba ise Hajji naa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَأَتِمُّوا الْحَجَّ وَالْعُمْرَةَ لِلَّهِ فَإِنْ أُحْصِرْتُمْ فَمَا اسْتَيْسَرَ مِنَ الْهَدْيِ وَلَا تَحْلِقُوا رُءُوسَكُمْ حَتَّى يَبْلُغَ الْهَدْيُ مَحِلَّهُ فَمَنْ كَانَ مِنْكُمْ مَرِيضًا أَوْ بِهِ أَذًى مِنْ رَأْسِهِ فَفِدْيَةٌ مِنْ صِيَامٍ أَوْ صَدَقَةٍ أَوْ نُسُكٍ فَإِذَا أَمِنْتُمْ فَمَنْ تَمَتَّعَ بِالْعُمْرَةِ إِلَى الْحَجِّ فَمَا اسْتَيْسَرَ مِنَ الْهَدْيِ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ فِي الْحَجِّ وَسَبْعَةٍ إِذَا رَجَعْتُمْ تِلْكَ عَشَرَةٌ كَامِلَةٌ ذَلِكَ لِمَنْ لَمْ يَكُنْ أَهْلُهُ حَاضِرِي الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ (196) " البقرة
'' Ki e se asepe ise Hajji ati Umura fun Olohun, sugbon ti won ba sin yin mo ona, ki e fi oun ti o ba rorun ni ore (ranse), ki ema si se fa (irun) ori yin titi ti ore naa yoo fi de aaye re. sugbon enikeni ninu yin ti o ba s'aisan tabi ti ori ndun un, ki o se irapada pelu (gbigba) awe tabi saara tabi eran pipa. Nigba ti e ba si ti fokanbale (ninu ewu), enikeni ti o ba pa Umura po mo Hajji, ki o fi oun ti o ba rorun se itore aanu. Sugbon enikeni ti ko ba ri (oun ti yoo fi se itore) ki o gba awe meta ni Hajji ki o si gba meje nigba ti o ba pada (de ile), eyi yoo je awe (ojo) mewa perepere, eyi wa fun eni ti kii se ara ilu makkah. Ki e beru Olohun. Ki esi mo pe Olohun le koko ni iya '' Q2:196.
5- Ninu irorun esin Islam ni abala Hajji sise tun ni pe, o se ni eto lati se mojemu nigba ti eniyan ba wa ninu ipaya awon oun ti o le sele si lori irin-ajo re, Aisha (Olohun ki o yonu si) sope:
" دخل رسول اللَّهِ صلى الله عليه وسلم على ضُبَاعَةَ بِنْتِ الزُّبَيْرِ فقال لها: " لَعَلَّكِ أَرَدْتِ الْحَجَّ ؟ " قالت: والله لَا أَجِدُنِي إلا وَجِعَةً فقال لها:" حُجِّي وَاشْتَرِطِي قولي: اللهم مَحِلِّي حَيْثُ حَبَسْتَنِي " متفق عليه
'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wole to Dubaa' omo Az-zubayr o si so fun pe: o jo pe o ngbero lati se Hajji? o si dahun wipe: mo fi Olohun bura pe ara nni mi, o si so fun wipe: daniyan Hajji naa sugbon ki o se mojemu ki o so wipe '' ire olohun aaye ibora-sile mi (ninu ise Hajji) ni ibi ti (aisan tabi ikagara) ba de bami '' (Al Bukari ati Muslim).
6- Ninu irorun esin Islam ni abala ise Hajji tun ni pe, o se ni okunfa aforijin ati ipare ese. Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) sope; Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" من حَجَّ هذا الْبَيْتَ فلم يَرْفُثْ ولم يَفْسُقْ رَجَعَ كيوم وَلَدَتْهُ أُمُّهُ " البخاري
'' enikeni ti o ba se irin-ajo (ise Hajji) wa si Ile yi ti ko so isokuso tabi wu iwa pokii yoo pada (si ile re) gegebi ojo ti iya re bi'' (Al Bukhari).

 

Irorun Esin Islam Lori Oro Obinrin
Obinrin je oun ti o ni ipo ti o ga ninu esin Islam, ti esin Islam si so iwo re, ti o si ka oro re kun, o se sise aponle re ni amin ije eniyan ti o loore ti adamo re ni alafia ti o si pe. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
 " أكمل المؤمنين إيمانا أحسنهم خلقا وخياركم خياركم لنسائهم " صحيح
'' eni ti o pe julo ni igbagbo ninu awon onigbagbo ododo ni eni ti iwa re dara julo, bakan naa ni pe eni ti o dara julo ninu yin ni eni ti o dara julo si awon obinrin (re) '' (Al Bukhari).
O se iwo re ni oun ti o gba iwaju iwo okunrin ni abala sise daadaa si ni, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe
" استوصوا بالنساء خيرا..." صحيح
'' o so asotele daadaa nipa awon obinrin ………'' (Al Bukhari).
Die ninu awon abala sise irorun pelu obinrin ni iwonyi:
1- Ninu sise irorun esin Islam ni abala awon obinrin ni pe, o se sisan owo ori re (mojemu fun jije iyawo) ni oranyan, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَآتُوا النِّسَاءَ صَدُقَاتِهِنَّ نِحْلَةً فَإِنْ طِبْنَ لَكُمْ عَنْ شَيْءٍ مِنْهُ نَفْسًا فَكُلُوهُ هَنِيئًا مَرِيئًا" النساء 4
'' Atipe ki e fun awon obinrin ni owo-ife (owo-ori) won ni tokan tokan, sugbon ti won ba fi idunnu yonda nkankan fun yin nibe funra won, nigba naa e je pelu irorun ati adun '' Q4:4.
2- Ninu irorun esin islam ni abala awon obinrin tun ni pe, o se ni eto fun lati gba owo-ife re ti oko re ba ko sile siwaju ki o to wole too, Olohun ti ola Re ga so pe:
" وَإِنْ طَلَّقْتُمُوهُنَّ مِنْ قَبْلِ أَنْ تَمَسُّوهُنَّ وَقَدْ فَرَضْتُمْ لَهُنَّ فَرِيضَةً فَنِصْفُ مَا فَرَضْتُمْ إِلَّا أَنْ يَعْفُونَ أَوْ يَعْفُوَ الَّذِي بِيَدِهِ عُقْدَةُ النِّكَاحِ وَأَنْ تَعْفُوا أَقْرَبُ لِلتَّقْوَى وَلَا تَنْسَوُا الْفَضْلَ بَيْنَكُمْ إِنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ " البقرة 237
'' Atipe bi eyin ba ko won sile siwaju ki e to fowo kan won, ti e si ti bu oranyan (owo-ife) sile fun won, nigbanaa idaji oun ti e ba bu ni oranyan (owo-ife) ni ki o ma je ti won, ayafi ti won ba se amoju kuro tabi ki eni ti itakoko yigi ba wa ni owo re se amoju kuro, atipe ki e se amoju kuro ni o sunmo iberu Olohun. Dajudaju Olohun ni Oluri oun ti e nse '' Q2:237.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala obinrin tun ni pe, ti oko re ba koo sile, ko leto lati le jade ninu ile re boya o le seese ki eleyi je okunfa ki won gba ara won pada. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِذَا طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ وَأَحْصُوا الْعِدَّةَ وَاتَّقُوا اللَّهَ رَبَّكُمْ لَا تُخْرِجُوهُنَّ مِنْ بُيُوتِهِنَّ وَلَا يَخْرُجْنَ إِلَّا أَنْ يَأْتِينَ بِفَاحِشَةٍ مُبَيِّنَةٍ وَتِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ وَمَنْ يَتَعَدَّ حُدُودَ اللَّهِ فَقَدْ ظَلَمَ نَفْسَهُ لَا تَدْرِي لَعَلَّ اللَّهَ يُحْدِثُ بَعْدَ ذَلِكَ أَمْرًا" الطلاق 1
'' Ire Anabi nigba ti e ba fe ko awon obinrin sile, nigbanaa ki eyin ko won pelu titele akoko won, ki eyin ka onka akoko naa (pe), ki eyin si paya Olohun Oluwa yin. Ki eyin ma se le won jade ninu ile won, atipe awon naa ko gbodo jade, ayafi ti won ba lo se ibaje ti o han gbangba. awon wonyi ni enu-aala Olohun, enikeni ti o ba tayo enu-aala Olohun, dajudaju o ti se abosi fun emi ara re. ire ko le mo boya Olohun le je ki oro miran sele leyin eyini '' Q65:1.
4- Ninu irorun esin islam ni abala obinrin tun ni pe, o pase nina owo lewon lori ati fifun won ni gbogbo eto won leyin igba ti won ba kowon sile, ki won se daadaa pelu re atipe won ko si gbodo fun le mo o titi ti yoo fi pari asiko igbele re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe
" أَسْكِنُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ سَكَنْتُمْ مِنْ وُجْدِكُمْ وَلَا تُضَارُّوهُنَّ لِتُضَيِّقُوا عَلَيْهِنَّ وَإِنْ كُنَّ أُولَاتِ حَمْلٍ فَأَنْفِقُوا عَلَيْهِنَّ حَتَّى يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ فَإِنْ أَرْضَعْنَ لَكُمْ فَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ وَأْتَمِرُوا بَيْنَكُمْ بِمَعْرُوفٍ وَإِنْ تَعَاسَرْتُمْ فَسَتُرْضِعُ لَهُ أُخْرَى" الطلاق 6
'' e fun won gbe ninu ibugbe yin bi aaye ba se gba yin mo, ki e si ma se ni won lara nipa fifun aaye mo won, ti won ba ni oyun nigbanaa ki e ma na owo fun won titi won yoo fi bi oyun inu won. Ti won ba ba yin fun omo ni omu, ki e fun won ni owo oya won, ki e si damoran laarin ara yin pelu daradara, ti oro yin ko ba papo, nigbanaa ki e gba (alagbato) omiran ki o fun lomu '' Q65:6.
5- Ninu irorun esin islam lori oro obinrin tun ni pe, o se itoju omo ni eto obinrin nigba ti o ba fe lati se bee, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَالْوَالِدَاتُ يُرْضِعْنَ أَوْلَادَهُنَّ حَوْلَيْنِ كَامِلَيْنِ لِمَنْ أَرَادَ أَنْ يُتِمَّ الرَّضَاعَةَ وَعَلَى الْمَوْلُودِ لَهُ رِزْقُهُنَّ وَكِسْوَتُهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ لَا تُكَلَّفُ نَفْسٌ إِلَّا وُسْعَهَا لَا تُضَارَّ وَالِدَةٌ بِوَلَدِهَا وَلَا مَوْلُودٌ لَهُ بِوَلَدِهِ وَعَلَى الْوَارِثِ مِثْلُ ذَلِكَ فَإِنْ أَرَادَا فِصَالًا عَنْ تَرَاضٍ مِنْهُمَا وَتَشَاوُرٍ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَا وَإِنْ أَرَدْتُمْ أَنْ تَسْتَرْضِعُوا أَوْلَادَكُمْ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِذَا سَلَّمْتُمْ مَا آتَيْتُمْ بِالْمَعْرُوفِ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ" البقرة 233
'' Ati ki awon abiyamo ma fun awon omo won lomu mu fun odun meji gbako fun eni ti o ba fe se asepe nibi fifun omo lomu mu, oranyan ni ije, imu ati aso wiwo je lori eni ti won bimo fun ni ona eto. A ko gbe ko emi kankan lorun ayafi iba agbara re. A ko gbodo ni abiyamo lara nitori omo re, bee si ni a ko gbodo ni baba lara nitori omo re pelu, iru eyi naa se oranyan fun eni ti yoo je ogun. Bi awon mejeeji ba si fe ja omu lenu omo ni ipanupo awon mejeeji ati ise asaro, ko si ese fun awon mejeeji. Ati bi e ba si fe fi awon omo yin fun alagbato, ko si ese fun yin nigba ti e ba ti fun won ni oun ti e fe fun won, ki e si beru Olohun, ki e si mo daju pe Olohun ri oun ti e nse '' Q2:233.
6- Ninu irorun esin Islam nipa oro obinrin tun ni pe, o se ninawo le lori ni eto yala nigba ti o ba wa ni iyawo labe oko tabi nigba ti won ba koo sile ti awon omo si wa pelu re leyin igba ti o ba pari asiko igbele re leyin kiko sile. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" لِيُنْفِقْ ذُو سَعَةٍ مِنْ سَعَتِهِ وَمَنْ قُدِرَ عَلَيْهِ رِزْقُهُ فَلْيُنْفِقْ مِمَّا آتَاهُ اللَّهُ لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا مَا آتَاهَا سَيَجْعَلُ اللَّهُ بَعْدَ عُسْرٍ يُسْرًا " الطلاق 7
'' eniti o ni oro (pupo) ki o na ninu pupo re, eniti a ba si diwon arisiki re (fun iwonba ipese), ki oun naa ki o na ninu oun ti Olohun se fun un, Olohun ko fi ko emi kankan lorun koja oun ti o fun un. Olohun yoo mu irorun wa leyin inira '' Q65:7.
7- Bakan naa ninu irorun esin Islam ni abala oro obinrin tun ni pe, o fun niipin tire ninu ogun leyin igba ti o ti je eniti ko leto si siwaju ki esin Islam to de. Olohun ti ola Re ga sope:
" لِلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ وَلِلنِّسَاءِ نَصِيبٌ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنْهُ أَوْ كَثُرَ نَصِيبًا مَفْرُوضًا " النساء 7ٍ
'' Awon okunrin ni ipin ninu oun ti awon obi ati ibatan (won) ba fi sile (ku), awon obinrin naa ni ipin ninu oun ti awon obi ati ibatan (won) ba fi sile (ku) ninu eyi ti o kere tabi ti o po, ipin ti a ti pinnu re ni " Q4:7.
8- Ninu irorun esin Islam ni abala oro obinrin tun ni pe, o yonda awon oranyan kan fun ni asiko ti o ba nse nkan osu tabi eje obi lowo, o yonda irun fun un ti ko si ni san-an pada ni igba miran, sugbon yoo san awe pada nigba ti o ba ni ikapani lati se bee. Mua'dhatu (Olohun ki o yonu si) sope:
" سَأَلْتُ عَائِشَةَ فقلت: ما بَالُ الْحَائِضِ تَقْضِي الصَّوْمَ ولا تَقْضِي الصَّلَاةَ ؟ فقالت: أَحَرُورِيَّةٌ أَنْتِ؟،قلت: لَسْتُ بِحَرُورِيَّةٍ وَلَكِنِّي أَسْأَلُ قالت: كان يُصِيبُنَا ذلك فَنُؤْمَرُ بِقَضَاءِ الصَّوْمِ ولا نُؤْمَرُ بِقَضَاءِ الصَّلَاةِ.(صحيح)
'' mo bi Aisha (Olohun ki o yonu si) pe: ki lo de ti eni ti o nse nkan osu yoo fi san awe pada sugbon ti ko ni san irun? o dahun wipe: nje okan ninu awon olu mu esin le koko lati ilu Haruura' ni iwo bi (Khawarij)? mo si dahun wipe rara mi o si ninu won (khawarij) sugbon mo nbeere ni, o wa dahun wipe: bayi ni o se ma nsele si wa (nkan osu), won si pawa lase sisan awe pada sugbon won ko pawa lase sisan irun pada '' (Al Bukhari).
Ninu iru awon nkan bayi ni tawaafu idagbere nibi ise Hajji fun obinrin ti nse nkan osu, Omo A'baas (Olohun ki o yonu si) sope:
" أُمِرَ النَّاسُ أَنْ يَكُونَ آخِرُ عَهْدِهِمْ بِالْبَيْتِ إِلَّا أَنَّهُ خُفِّفَ عَنْ الْمَرْأَةِ الْحَائِضِ "مُتَّفَقٌ عَلَيْهِ
'' won pa awon eniyan lase pe ki o jepe asekanhin ise won pelu Ile naa je (Tawaafu), sugbon won yonda re fun obinrin ti nse nkan osu lowo " (Al Bukari ati Muslim).
9- Bakan naa ninu irorun esin Islam fun obinrin tun ni pe, o se ni eto pe ki oun ati oko re gbadun ara won ni asiko ti o nse nkan osu lowo ni gbogbo ona ayafi ibalopo nikan. Anas (Olohun ki o yonu si) sope: '' Awon yehuudi ko ki nba awon obinrin won jeun papo nigba ti won ba nse nkan osu lowo bee si won kii ba won gbe papo ni asiko naa. Awon omoleyin Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa beere nipa re, bayi ni Olohun ti ola Re ga so oro Re kale bayi pe:
'' Won yoo bi o leere nipa nkan osu (obinrin), sope: egbin ni, nitori naa e ya fun awon obinrin ni asiko naa ki e ma si se sunmo won titi won yoo fi mo. Nigba ti won ba mo ki e lo ba won ni aaye ti Olohun pa lase fun yin, dajudaju Olohun feran awon ti o ronu piwada O si feran awon ti o mo " Q2:222.
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si so leyin ese oro yi pe:
:" اصْنَعُوا كُلَّ شَيْءٍ إلا النِّكَاحَ " رَوَاهُ مُسْلِم
'' e se gbogbo nkan patapata (ninu igbadun loko laya) ayafi ibalopo nikan '' (Muslim).
10- Ninu irorun esin Islam ni abala oro obinrin tun ni pe, ko se ni ojuse fun won kiko pa ninu ogun nigba ti o ba sele. Aisha (Olohun ki o yonu si) sope:
" يا رسول الله هل على النساء من جهاد ؟، قال:" نعم عليهن جهاد لاقتال فيه الحج والعمرة " رواه أحمد صحيح.
'' ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nje obinrin ni ogun (esin) ti o le ja bi? o si dahun wipe beeni won ni ogun (esin) ti won le ja ti ko ni ija (oko ati ada) ninu, Hajji (sise) ati Umurah '' (Ahmad).
11- Ninu irorun esin Islam ni abala oro obinrin tun ni pe, ko se ise sise, inawo ati gbigbo bukata (ile oko re) ni oranyan le lori.

Irorun Esin Islam Ni Abala Owo Sise (Kata-Kara)
Owo (dukia) je oun pataki ninu isemi-aye, atipe orisirisi asawo (ijanba) ni o ma nwonu owo sise awon eniyan gegebi itanje, abosi, gbigba eto-eleto pelu tipatipa ati gbigbe ola fun anfaani ara-eni lai bikita awon aburu ti o le ti eyin re yo fun elomiran. Eleyi ni o si so di pataki pe ki irorun ati irora joba laarin awon eniyan ni abala yi bakan naa.
 Die ninu apejuwe irorun esin Islam ni abala yi ni wonyi:
1- Ninu irorun esin Islam ni abala tita ati rira ni pe, o seni lojukokoro sise irorun ati irora nibe. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" رحم الله امرءً سمحاً إذا باع سمحاً إذ اشترى..."البخاري
'' Olohun ki o ke omoniyan kan ti o se irorun nigba ti o ba ta (oja) ati ti o ba ra (oja)…..'' (Al Bukhari).
2- Ninu irorun esin Islam ni abala yi tun ni pe, o seni lojukokoro ki a fara de onigbese pelu sisun asiko ati sisan gbese seyin fun un ki o le ni anfaani lati san gbese ti o je, tabi ki a tile mu die kuro fun-un ninu iye ti o je ni gbese ti o si jepe eleyi ni o dara julo lodo Olohun. Olohun ti ola Re ga sope:
" وَإِنْ كَانَ ذُو عُسْرَةٍ فَنَظِرَةٌ إِلَى مَيْسَرَةٍ وَأَنْ تَصَدَّقُوا خَيْرٌ لَكُمْ " البقرة 280
'' Bi o (onigbese naa) ba je eni ti ara nni ki e lo o lara di igba ti yoo rorun (fun un). Atipe ki e tore (fun un) ni o dara ju fun yin bi eyin ba mo ni '' Q2:280. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" من أَنْظَرَ مُعْسِرًا كان له بِكُلِّ يَوْمٍ صَدَقَةٌ وَمَنْ أَنْظَرَهُ بَعْدَ حِلِّهِ كان له مِثْلُهُ في كل يَوْمٍ صَدَقَةٌ " ابن ماجة وصححه الألباني
'' enikeni ti o ba lo eniti ara nni lara, lori ojo kookan (ti o fi loo lara) yoo ma gba esan itore aanu, bakan naa enikeni ti o ba lo o lara leyin igba ti ojo ati sisan gbese ti pe, lori ojo kookan (ti o fi lo o lara) yoo ma gba esan itore-aanu ti o se deedee re (iye gbese naa) '' (Ibn Hiban).
3- Ninu irorun esin Islam ni abala tita ati rira tun ni pe, o seni lojukokoro ki a se pelepele nigba ti a ba nsin-wo (gbese). Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" حُوسِبَ رَجُلٌ مِمَّنْ كان قَبْلَكُمْ فلم يُوجَدْ له من الْخَيْرِ شَيْءٌ إلا أَنَّهُ كان يُخَالِطُ الناس وكان مُوسِرًا فَكَانَ يَأْمُرُ غِلْمَانَهُ أَنْ يَتَجَاوَزُوا عن الْمُعْسِرِ" قال: قال الله عز وجل:" نَحْنُ أَحَقُّ بِذَلِكَ منه تَجَاوَزُوا عنه " مسلم
'' won se isiro ise arakunrin kan ninu awon (ijo) ti o siwaju yin, won ko ri daradara kankan ni akosile fun-un, ayafi wipe o je eni ti o ma nba awon eniyan sepo, o si je eni ti o lowo lowo, o si ma npa awon osise re lase wipe ki won yonda (gbese) eni ti ara ba nni '' Olohun ti ola Re ga wa so bayi pe: Awa ni A leto lati maa se bayi (yiyonda gbese feni ti ara nni), nitorinaa e mojukuro (nibi ese) fun oun naa '' (Muslim).
4- Ninu irorun esin Islam tun ni pe, o seni lojukokoro lori ki a san gbese ni ona ti o dara julo, Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) sope arakunrin kan wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lati sin owo (gbese) re, sugbon o lo ona ti ko ye (ti o le koko) lati sin owo re, bayi ni awon Sahaba si gbero lati fi enu abuku kan an, sugbon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun won pe:
"دَعُوهُ فإن لِصَاحِبِ الْحَقِّ مَقَالًا ثُمَّ قال أَعْطُوهُ سِنًّا مِثْلَ سِنِّهِ قالوا يا رَسُولَ اللَّهِ لا نجد إلا أَمْثَلَ من سِنِّهِ فقال أَعْطُوهُ فإن من خَيْرِكُمْ أَحْسَنَكُمْ قَضَاءً" متفقٌ عَلَيْهِ.
'' e fi sile nitoripe dajudaju eni ti o ni eto ni anfaani lati soro. Leyin naa ni o so pe: e fun ni (rakunmi) ti o se deedee iru tire ni ojo ori, won si dahun wipe: ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) a ko ri ayafi eyi ti o dagba ju tire lo, o si da won lohun wipe: e fun un, nitoripe dajudaju eni ti o loore julo ninu yin ni eni ti o dara julo ni isan gbese '' (Al Bukari ati Muslim).
5- Ninu irorun esin Islam ni abala tita ati rira tun ni pe, o seni loju kokoro ki a gba oja ti olura tabi oluta ba da pada latara ikabamo re (lori oja naa). Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe
" من أقال نادما بيعته أقال الله عثرته يوم القيامة " صحيح.
'' enikeni ti o ba gba oja pada lowo eni ti o kabamo lori oun tira, Olohun yoo gbe inira ati asise re kuro ni ojo igbende '' (Al Bukhari).
6- Ninu irorun esin Islam ni abala tita ati rira tun ni pe, o se leto fun oluta ati olura lati se esa laarin ara won, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:  
" الْبَيِّعَانِ بِالْخِيَارِ ما لم يَتَفَرَّقَا أو قال حتى يَتَفَرَّقَا فَإِنْ صَدَقَا وَبَيَّنَا بُورِكَ لَهُمَا في بَيْعِهِمَا وَإِنْ كَتَمَا وَكَذَبَا مُحِقَتْ بَرَكَةُ بَيْعِهِمَا" البخاري
'' oluta ati olura ni anfaani lati sesa laarin ara won niwonba igba ti won ko ba tii tuka (ti won si wa papo ni aaye iduna dura), tabi titi ti won yoo fi tuka, ti won ba so ododo (fun ara won) ti won si salaye (nipa oja ti won fe ra tabi ta) won (Olohun) yoo fi ibukun (alubarika) si oja awon mejeeji, sugbon ti won ba fi (nkankan) pamo ti won si pa iro (fun ara won) won (Olohun) yoo mu ibukun (alubarika) kuro lori oja awon mejeeji '' (Al Bukhari).
7- Ninu irorun esin Islam ni abala ibasepo ni abala owo tun ni pe, o gbe ilana kale lori bi a se gbodo pin ogun fun awon ti oku fi sile ti won si leto si ogun re, yala omode ni tabi agbalagba, okunrin tabi obinrin, o gbe kale ni ona deedee ti ko legbe, ti gbogbo onilakaye pipe eniyan siri bee. Ipin naa wa lori bi awon eniyan wonyi se sunmo tabi jinna si oku si, o si wa lori anfaani oku ti o jepe oun ni o ni dukia naa. Ko leto fun enikankan lati pin ogun ni ibamu si ife inu re. Ninu anfaani ilana ipin-gun yi ni pe, bi o ti wu ki oro naa po to yoo pin welewele si kekere kekere, yio sise ki dukia fiditi si odo awon iko perete kan ni oun ti ko seese ti ko si rorun.
 Al-kurani alaponle ti se alaye yekeyeke ipin okikaluku ninu omo, obi iyawo ati awon omo-iya, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" يُوصِيكُمُ اللَّهُ فِي أَوْلَادِكُمْ لِلذَّكَرِ مِثْلُ حَظِّ الْأُنْثَيَيْنِ فَإِنْ كُنَّ نِسَاءً فَوْقَ اثْنَتَيْنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَ وَإِنْ كَانَتْ وَاحِدَةً فَلَهَا النِّصْفُ وَلِأَبَوَيْهِ لِكُلِّ وَاحِدٍ مِنْهُمَا السُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِنْ كَانَ لَهُ وَلَدٌ فَإِنْ لَمْ يَكُنْ لَهُ وَلَدٌ وَوَرِثَهُ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ الثُّلُثُ فَإِنْ كَانَ لَهُ إِخْوَةٌ فَلِأُمِّهِ السُّدُسُ مِنْ بَعْدِ وَصِيَّةٍ يُوصِي بِهَا أَوْ دَيْنٍ آبَاؤُكُمْ وَأَبْنَاؤُكُمْ لَا تَدْرُونَ أَيُّهُمْ أَقْرَبُ لَكُمْ نَفْعًا فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا" النساء 11
'' Olohun npase fun yin nipa (ogun) awon omo yin, okunrin kan yoo ma ni ipin obinrin meji, sugbon ti won ba je obinrin ti o ju meji lo, won yoo ni idameji idameta oun ti o (oku) ba fi sile, bi o ba si je (omobinrin) okansoso ni, idaji ni tire, nbe fun awon obi re, idafa (idakan ninu mefa) fun eni okookan ninu won ninu oun ti o fi sile, bi omo ba nbe nile fun un, sugbon ti ko ba si omo (kankan) fun un ti o je pe awon obi re ni yoo jogun re, nagba naa iya re yoo ni idata, sugbon bi awon arakunrin tabi arabinrin (omo iya ati baba) ba nbe fun un, iya re yoo ni idafa leyin aso-sile ti o so tabi gbese, awon baba yin ati awon omo yin e ko mo ewo ninu won ni o sunmo yin julo ni ti anfaani. Oranyan ni lati odo Olohun, dajudaju Olohun je Oluni-imo Ologbon '' Q4:11.
 Yato si awon alaye ti Olohun tun se ni awon orisirisi aaye ninu Al-Kurani ti aaye ko le gba wa lati se alaye ninu iwe yi sugbon ti alaye nbe ninu awon iwe ti o soro nipa ogun pinpin.
8- Bakan naa ninu irorun esin Islam ni abala ogun pinpin tun ni pe, o se ni eto ki a fun awon ti o wa nibi ti a ti npigun ninu re nigba ti a ba npin lowo ki a ma si se gbagbe won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَإِذَا حَضَرَ الْقِسْمَةَ أُولُو الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينُ فَارْزُقُوهُمْ مِنْهُ وَقُولُوا لَهُمْ قَوْلًا مَعْرُوفًا " النساء 8
'' Nigbati awon ibatan ati omo-orukan ati alaini ba nbe nibi ipin (ogun). E fun won ninu re ki e si ba won so oro itunu '' Q4:8.
9- Ninu irorun esin Islam bakan naa ni abala yi tun ni pe, o fi ofin sise asotele (fifi ipin kan tore) lele. Musulumi ni anfaani lati so asotele ninu dukia re leyin iku re leyi ti won yoo lo fun daadaa ati ise rere ti yoo ma je itore-aanu lailai fun leyin iku re. Bi o tile-jepe asotele ni onde ati mojemu wipe ko gbodo koja idakan ninu idameta gbogbo dukia oku. Aa'mir omo Saee'd sope:
" كان النبي صلى الله عليه وسلم يعودني وأنا مريض بمكة فقلت لي مال أوصي بمالي كله قال لا قلت فالشطر قال لا قلت فالثلث قال الثلث والثلث كثير أن تدع ورثتك أغنياء خير من أن تدعهم عالة يتكففون الناس في أيديهم ومهما أنفقت فهو لك صدقة حتى اللقمة ترفعها في في امرأتك ولعل الله يرفعك ينتفع بك ناس (من المؤمنين) ويضر بك آخرون (من الكفار) "
'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eniti o ma nbe miwo ni asiko ti mo ns'aisan ni ilu Makkah. Mo wa sope: mo ni dukia (ti o po), nje mo le so asotele pelu gbogbo re bi? O si dahun wipe: rara, mo tun sope: idaji nko? o tun dahun wipe: rara, mo tun sope: idameta re nko? o si dahun wipe: idameta, idameta naa po, o ri ki o fi awon olujogun re sile ni aboro o loore ju ki o fi won sile ni olosi (talika) ti won yoo wa ma toro lowo awon eniyan. Bayiowu ti o ba naa, itore-aanu ni yoo je fun o, koda ti o fi dori okele ti o fi s'enu iyawo re. Osi seese ki Olohun gbe o ga nipo ki awon eniyan kan (onigbagbo ododo) si se anfaani pelu re, ki awon miran (keferi) si kan inira pelu re ''
 Bakannaa ninu mojemu asotele ni pe ko si fun eniti o leto ninu ogun ki o ma ba ko inira ba awon yoku ti yoo jogun, tabi ki o ma ba da ota ati ikorira sile laarin won. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إن الله قد أعطى كل ذي حق حقه فلا وصية لوارث"صحيح
'' Olohun ti fun eniti o ni eto ni eto re, nitorinaa ko si asotele fun eniti yoo jogun '' (Al Bukhari).

Irorun Esin Islam Ni Abala Idiyaje
 Esin Islam se agbekale gegebi awon esin miran eto idiyaje eyi ti o je ona lati mu ifokanbale ati mimu awujo la kuro ninu awon iwa ibaje ati fifankan re, o je okunfa siso emi ati iyi ati aponle, o si je okunfa siso dukia, o si je igbogunti fun awon alaburu awujo, o si je iso fun awon eniyan nibi ki won ma fi aburu kan ara won. Idiyaje yi je idena fun sisele ibaje tabi ki a sope o ma ndin sisele re ku.
 Eleyi ni o si fa ti esin Islam fi gbe ijiya ti o se deede kale fun iwa-ibaje kookan ni ibamu si bi won se tobi to. Nitorinaa o se ijiya imoomo-paniyan ni pipa eni ti o paniyan dipo, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:     
 " يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِصَاصُ فِي الْقَتْلَى "
'' Eyin onigbagbo ododo A pa igbesan lase fun yin nipa ipaniyan ..'' Q2:178.
Ayafi ti awon ara-ile oku ba se amojukuro, nitori oro Olohun ti ola Re ga ti o so pe:
" فَمَنْ عُفِيَ لَهُ مِنْ أَخِيهِ شَيْءٌ..."
'' Sugbon eni ti a ba se idarijin nkankan fun lati odo omo-iya (ti won pa eniyan re)….'' Q2:178.
 Bakan naa o se ijiya ole-jija ni owo-gige, Olohun ti ola Re ga so pe:
" وَالسَّارِقُ وَالسَّارِقَةُ فَاقْطَعُوا أَيْدِيَهُمَا جَزَاءً بِمَا كَسَبَا نَكَالًا مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ (38) "
'' Ole l'okurin ati ole l'obinrin, e ge owo awon mejeeji ni esan fun ise awon mejeeji, arikogbon lati odo Olohun. Olohun ni Alagbara, Ologbon '' Q5:38.
Nigbati ole ba mo wipe ti oun ba ja'le won yoo ge oun lowo, yoo jawo nibi ole-jija, yoo si so owo re kuro nibi ki won ge e, bakanaa ni dukia awon eniyan yoo si la kuro nibi jiji.
 O si se ijiya agbere ati pansaga ni egba-jije (nina) fun eniti ko ni iyawo tabi oko. Olohun ti ola Re ga so pe:
" الزَّانِيَةُ وَالزَّانِي فَاجْلِدُوا كُلَّ وَاحِدٍ مِنْهُمَا مِائَةَ جَلْدَةٍ "
'' Alagbere l'obinrin ati alagbere l'okunrin, e na enikookan ninu awon mejeeji ni egba ogorun '' Q24:2.
Eleyi je odi iso kuro nibi idaru-dapo iran (mo iran miran), o si je odi iso fun dukia awon eniyan kuro nibi ki eni ti kii se iran won je ogun won.
 O si se ijiya pipa iro agbere mo eni ti ko se e, ni egba-jije bakanaa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَالَّذِينَ يَرْمُونَ الْمُحْصَنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَأْتُوا بِأَرْبَعَةِ شُهَدَاءَ فَاجْلِدُوهُمْ ثَمَانِينَ جَلْدَةً " النور 4
'' Awon ti won npe pasanga mo awon obinrin ti won kii se oni pansaga, leyin naa ti won ko ri eleri merin muwa, e na won ni ogorin egba e ko si gbodo gba eri won lailai, awon eleyi ni pokii '' Q24:4.
 Ati awon miran ninu awon iwa ibaje ti esin Islam fi awon ijiya orisirisi ti o se deedee lele fun nitori ewu ti o ro mo ninu awujo. Leyin naa ni ilana ofin esin wa fi ipile pataki kan lele ti gbogbo ijiya patapata duro le lori, Olohun ti olaRe ga so bayi pe:
" وَجَزَاءُ سَيِّئَةٍ سَيِّئَةٌ مِثْلُهَا "
'' Atipe oun ti o je buburu buburu naa ni esan re…. '' Q42:40.
Ati oro Olohun ti ola Re ga tio so bayi pe:     
" وَإِنْ عَاقَبْتُمْ فَعَاقِبُوا بِمِثْلِ مَا عُوقِبْتُمْ بِهِ "
'' Ti eyin ba si fe gba esan (iya), ki e gba esan ni iru iya ti won ba fi jeyin '' Q16:126.
Gbogbo awon oniranran ijiya yi ni o ni awon mojemu ati onde ti a gbodo woye si nibi lilo re.
1- Ninu irorun esin Islam ni abala idiyaje eyi ti o sopo mo eto omoniyan ni pe, ko se idiyaje naa ni oranyan ti ko gbodo mo sele, bikosepe o se ni oun ti anfaani aforijin ati amojukuro wa fun tabi sisan nkan gba-mabinu. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَجَزَاءُ سَيِّئَةٍ سَيِّئَةٌ مِثْلُهَا فَمَنْ عَفَا وَأَصْلَحَ فَأَجْرُهُ عَلَى اللَّهِ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الظَّالِمِينَ (40)"
''Atipe oun ti o je buburu buburu naa ni esan re, enikeni ti o ba si mojukuro ti o si se atunse, esan re nbe lodo Olohun, dajudaju Oun ko ni fe awon alabosi '' Q42:40.
2- Ninu irorun esin Islam ni abala idiyaje tun ni pe, oun ti o ba sopo mo eto Olohun, niwonba igba ti omoniyan ko ba mo se ni gbangba ti oro re ko si tii de odo awon alase ti won yoo se imuse ijiya ofin, a ko ni lo ofin ijiya naa le lori, nitoripe oro naa wa laarin oun ati Oluwa re. Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) sope: Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" كل أمتي معافى إلا المجاهرون وإن من المجانة أن يعمل الرجل عملا بالليل ثم يصبح وقد ستره الله فيقول يا فلان عملت البارحة كذا وكذا وقد بات يستره ربه ويصبح يكشف ستر الله عنه " متفق عليه
'' Gbogbo ijo mi ni eni aforijin ayafi olufibaje sayo (olusebaje ni asehan), atipe dajudaju ninu iwa omugo, ailojuti ati ifi-ese-se awewa ni ki eniyan sise (aburu) kan loru ki o wa di ni owuro leyin ti Olohun ti boo lasiri, ki o ma sope '' ire lagbaja, mo se bayi bayi ni ana (oru moju) '' leyin igba ti Olohun ti bo o lasiri ni oru, ki o wa ji ni owuro ki o ma tu asiri naa (ni ti iyanran) ti Olohun ti bo '' (Al Bukari ati Muslim).
 Dajudaju esin Islam ko sa dede gbe awon idiyaje wonyi kale bikosepe lati fi so eto ati iwo omoniyan ati lati fi alafia ati ifokanbale lole laarin awujo ati ki ilu la kuro ninu iwa ibaje, bakanna lati dena mo gbogbo eni ti emi re ba npe e lo sibi dida irowo rose ati alafia ilu laamu. Nigba ti apaniyan ba mo wipe ijiya ese oun ni ki won pa oun naa pada, ti ole si mo wipe ijiya ese oun ni ki won ge owo oun, ti alagbere si mo wipe ijiya ese oun ni ki won na oun le'gba, onikaluku won ni yoo jawo ninu aburu wonyi. Ododo ni oro Olohun ti ola Re ga ti o so pe:
" وَلَكُمْ فِي الْقِصَاصِ حَيَاةٌ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ (179) "
'' Isemi nbe fun yin ninu igbesan, eyin ti e ni lakaye, ki e ba le sora yin '' Q2:179.
 O seese ki a ri eni ti yoo sope awon ijiya wonyi ti esin Islam gbe kale fun awon iwa ibaje kookan ti lagbara ju! idahun nipe: dajudaju gbogbo omoniyan ti o je onilakaye ni yoo gba pe ikookan awon iwa ibaje wonyi ni o ni oniranran inira ati aburu ti o ko sinu ti ko si pamo si gbogbo eniyan. Nitori idi eyi oranyan ni ki awon oun ti yoo je idena, igbogunti ati idiyaje wa fun un. Bi ese kookan se ri naa si ni ijiya re ri, eleyi lo si fa ki ijiya orisirisi wa.
Ti onikaluku ba bi ara re leere ti o si woye si awon ijiya kookan ti esin Islam gbe kale yoo ri pe oun ni o se deedee ti o si ni aseyori nibi didena awon iwa ibaje wonyi yala ki o wu u tegbo-tegbo ni tabi ki o din-in ku ninu awujo. Sugbon ti a ba woye si awon idiyaje atowoda (eyi ti omoniyan gbe kale) fun ra won, a o ri pe ko din nkankan ku ninu aburu wonyi bikosepe o tun nse alekun re ni, koda o tun seese ki onibaje odaran eniyan ri ona abayo nibe ki alare si di elebi. Nitorinaa ika to ba se loba a ge ki awon orikerike ara yoku le ni alafia.

Irorun Esin Islam Ni Abala Ogun kiko ni Leru
Ninu eyi ti ko si iyemeji nbe nipe, aigbora-eniye ati ogun jija je adamo awujo omoniyan, yala latara yiyato iran won ni tabi esin won tabi iyapa-enu tabi ogun latari ijegaba, ifowo-ola gbani-loju tabi nitori alamori oro-aje. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلَوْلَا دَفْعُ اللَّهِ النَّاسَ بَعْضَهُمْ بِبَعْضٍ لَفَسَدَتِ الْأَرْضُ وَلَكِنَّ اللَّهَ ذُو فَضْلٍ عَلَى الْعَالَمِينَ (251) "
'' Atipe ti ko ba je pe Olohun nfi apakan awon eniyan dabo bo apakan won ni dajudaju ile naa ko ba ti baje, sugbon Olohun je Olola si gbogbo eniyan '' Q2:251.
Sugbon ninu esin Islam ogun jija wa lori ibanilo niti omoniyan eyi ti ko legbe, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ خَرَجُوا مِنْ دِيَارِهِمْ بَطَرًا وَرِئَاءَ النَّاسِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ " الأنفال 48
'' E mase da gege bi awon ti won jade ninu ile (ilu) won ni ti igberaga ati sekarimi, ti won si nseri (awon eniyan) kuro loju ona Olohun '' Q8:48.
 Ninu awon idi pataki ti esin Islam fi gbe ogun jija kale ni idena ati kikodi ota ati sise iranlowo fun eni ti won se abosi re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَمَا لَكُمْ لَا تُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ وَالْوِلْدَانِ الَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْ هَذِهِ الْقَرْيَةِ الظَّالِمِ أَهْلُهَا وَاجْعَلْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ وَلِيًّا وَاجْعَلْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ نَصِيرًا" النساء 75
'' kini wa lo seyin ti eyin o fi ja si oju ona ti Olohun ati (nigbati) awon alailagbara ninu awon okunrin ati awon obinrin ati awon omode, awon ti nsope: Oluwa wa, muwa jade kuro ninu ilu yi ti awon ara inu re je alabosi, ki O si fun wa ni oludaabobo kan lati odo Re, ki o si fun wa ni oluranlowo kan lati odo Re '' Q4:75.
Nigbati Ogun jija ninu esin Islam koyekogbo ni eyi ti o duro lori ibanilo niti omoniyan, o je dandan ki abala irorun ati irora fojuhan nibe gbangba, fun apere:
1- Ninu irorun ati irora esin Islam ni abala yi ni pe, ki se esin igbesumomi, ikoja'la, abosi tabi esin ogun nikan (jagijagan) gegebi awon ota esin (ti pipo awon ti nse esin naa tabi ti nwonu re nbi ninu) se ma n royin re, iroyin won yi jinna si ododo, nitoripe Olohun ti ola Re ga ko fun ni nibi ikoja'la ninu oro Re ti O si o bayi pe:
" وَقَاتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَكُمْ وَلَا تَعْتَدُوا إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْمُعْتَدِينَ (190) "
'' Ki e si maa ba won ja l'oju ona Olohun awon eniti won nba yin ja, sugbon ki e ma se rekoja ala, dajudaju Olohun ko feran awon ti n rekoja ala '' Q2:190.
2- Ninu irorun esin Islam ni abala ogun jija tun ni pe, o pa awon musulumi lase lasiko ti won ba njagun lowo pelu awon ota won pe ki won fi aaye ijoko alafia sile ti won (awon ota won) ba fe bee, eleyi ti nsalaye pe esin Islam kii se esin ti o duro lori ipaniyan tabi ita eje sile. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَإِنْ جَنَحُوا لِلسَّلْمِ فَاجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ (61) " الأنفال
'' Ti won ba te si (wa ijoko) alafia ki iwo naa te sii ati ki o si gbara le Olohun, dajudaju Oun ni Olugboro, Onimimo '' Q8:61.
3- Ninu irorun esin Islam ni abala ogun jija tun ni pe, o pase pe a ko gbodo pa eni ti ko bawa jagun (gbogun ti wa).
4- Bakanna, ninu irorun esin Islan ni abala ogun jija tun ni pe, o ni awon onde ati eko ti o sopo mo, nitori ki o ma ba mu kuro lori ilomoniyan ti o duro le lori. A ko gbodo pa ota kankan ayafi eni ti o ba kopa ninu ogun ti o si nse iranlowo lori re. Sugbon awon agbalagba, awon omode, awon obinrin, awon alaisan ati awon ti ntoju awon alaisan ati awon ti won fara gbogbe (awon dokita ati awon oluranlowo won) pelu awon ti won nse ijosin ninu awon aaye ijosin a ko gbodo pa won.
 Bakan naa ni ko leto ka pa eni ti o o fara gbogbe loju ogun, a ko si gbodo se oku ni isekuse (apatunpa), beeni a ko gbodo pa eranko, a ko si gbodo wo ile tabi ko egbin ba omi tabi odo atipe a ko gbodo le eni ti o ba sa kuro loju ogun. Awon eko wonyi ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ati awon arole re (Olohun ki o yonu si gbogbo won) ma nso fun awon asiwaju ogun.
Apejuwe ilana ijagun ninu esin Islam ti o duro lori irorun ati irora je eyi ti o farahan ninu isesi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nigba o gba ilu Makkah, ti o si jepe awon eniyan wonyi ni won le jade ti won fi suta orisirisi kan an ti won si pa opolopo ninu awon omoleyin re, ti won si tun petepero lori bawo ni won yoo se pa oun naa, sugbon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) yi ni o so nigba ti o wo ilu Makkah wipe:
من دخل دار أبي سفيان فهو آمن، ومن أغلق بابه فهو آمن، ومن ألقى السلاح فهو آمن.
'' enikeni ti o ba wo ile Abu Sufyan eni ifokanbale nii se, enikeni ti o ba ti ilekun mori eni ifokanbale nii se, enikeni ti o ba so nkan ija re danu eni ifokanbale nii se.
 Awon arole re naa (Olohun ki o yonu si gbogbo won) won koye won kogbo lori oju ona irorun ati irora nibi ogun jija ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fi lele leyin igba ti o lo tan. Abu Bakri (Olohun ki o yonu si) ti o je arole alakoko fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun awon olori ogun ti o ran lo si ogun wipe:
" قفوا أوصيكم بعشر فأحفظوها عني:" لاتخونوا، ولا تغلوا(تسرقوا)، ولاتغدروا، ولاتمثلوا(تشوهوا)، ولاتقتلوا طفلاً صغيراً، ولا تقتلوا شيخاً ولا امرأة، ولاتعقروا(تقطعوا) نخلاً ولاتحرقوه، ولاتقطعوا شجرة مثمرة، ولاتذبحوا شاة ولابقرة ولابعيراً إلالمأكلة، وسوف تمرون بأقوام قد فرغوا أنفسهم في الصوامع فدعوهم وما فرغوا أنفسهم له "
'' e duro ki nso awon asotele mewa kan fun yin, ki e ri pe e se amojuto won daada,: '' e mase ijanba, e ma jale, e ma se itanje, e ma paniyan ni ipakupa, e ma pa omode kekere, e ma pa arugbo tabi obinrin, e ma ge igi ope (tamaru) e ko gbodo f'ina si, e ko gbodo ge igi eleso, e ko gbodo pa yala ewure ni tabi maalu tabi rakunmi bikosepe e ba fe jee, e o ri awon eniyan kan ti won juwo ara won sinu awon ile ijosin e fi won sile pelu oun ti won nse ''
5- Ninu irorun esin Islam ni abala ogun jija tun ni pe, o gbe ilana sise aponle eto ati biba awon ti a ko leru ni ibalo omoniyan kale. O je ki o yewa pe ko leto ki a f'iya je –won, tabi ki a fi iyepere kan won, tabi ki a ko ipaya ati jinni-jinni bowo, tabi ki a pa won ni ipakupa, tabi ki a ko fun won nibi jije ati mimu titi ti won yoo fi ku. Bikosepe ki a se aponle won ki a si bawon lo pelu daadaa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَيُطْعِمُونَ الطَّعَامَ عَلَى حُبِّهِ مِسْكِينًا وَيَتِيمًا وَأَسِيرًا (8) إِنَّمَا نُطْعِمُكُمْ لِوَجْهِ اللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنْكُمْ جَزَاءً وَلَا شُكُورًا (9) "
'' Atipe won a ma nfun awon alaini ati awon omo orukan ni ounje, ti awon naa si nife si lati je e, ati awon ti won wa loko eru \\ (Nwon a si ma sope) Dajudaju awa ko tori nkankan fun yin ni oun jeje bikosepe lati wa ojure Olohun, atipe awa ko wa esan kankan tabi ope kankan ni odo yin '' Q76:8-9.
Ilana ibanilo pelu sise aponle ijeomoniyan yi ni awon elesin Islam nlo lati ba awon ti won ba ko leru lo lati oju aye Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Okan ninu awom omo-iya Mus'ab omo Umayr (Olohun ki o yonu si) ti oruko nje Abu Azeez nso nipa isele ti o sele si ni oju ogun Badri bayi pe:
 " كنتُ في الأسرَى يومَ بدرٍ فقال رسولُ اللهِ صلَّى اللهُ عليه وسلَّم " استوصوا بالأسارَى خيرًا " وكنتُ في نفرٍ من الأنصارِ فكانوا إذا قدموا غداءَهم وعشاءَهم أكلوا التمرَ وأطعموني البرَّ لوصيةِ رسولِ اللهِ صلَّى اللهُ عليه وسلَّم "
'' mo wa ninu awon ti won ko leru loju ogun Badri, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa so bayi pe: '' e ripe e se asotele daadaa nipa awon eru wonyi (e bawon lo pelu daadaa) '', mo si wa laarin awon iko kan ninu awon Ansaar, igbakugba ti won ba gbe ounje osan tabi ti ale de won yoo je eso tamoru won yoo si fun awa ni alikamo (oka ti o wa nibe) je latari asotele Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)! ''
6- Ninu iroru esin Islam ni abala ogun jija tun ni pe, o pase ki a ba awon ti a fe gba ilu won (ba jagun) lo ni ibalo ti o dara. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so asotele daadaa lori awon ara ilu Misira nigba ti o so pe:
" إذا فتحتم مصر فاستوصوا بالقبط خيرًا، فإن لهم ذمة ورحمًا " صحيح مسلم
'' nigba ti e ba si ilu Misra, e se asotele daadaa pelu awon ara ilu Misra, nitoripe won ni iwo (lorun wa) ati okun ebi (pelu wa) '' (Muslim).
 Awon eniyan ti won ba bori won logun ninu awon ilu won ko gbodo fi omoluabi won yile, tabi gba dukia won, tabi ki won yepere iyi won, tabi ki won si fi abuku kan won, tabi ki won ba ilu won je, nigba ti o jepe (ogun won) kii se ti ibinu tabi igbesan, bikosepe o je ona atunse, ipase daadaa ati iko iwa ibaje pelu fifi deedee lele. Awon musulumi tele ilana Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nibi ogun jija leyin re.
 Ninu awon itokasi ati apejuwe lori eleyi ni adehun eyi ti Umar omo Khatab (Olohun ki o yonu si) se fun awon ara ilu Jerusalemu nigba ti o wo ilu naa, ti o so bayi pe:
 ( بسم الله الرحمن الرحيم هذا ما أعطى عبد الله عمر بن الخطاب أمير المؤمنين أهل المقدس من أمان: أعطاهم أماناً على أنفسهم وأموالهم ولكنائسهم وصلبانهم.... ولايكرهون(يجبرون) على دينهم ولايضار أحد منهم... )
(Ni oruko Olohun Ajoke aye Asake orun, eleyi ni adehun ti erusin Olohun Umar omo Khatab asiwaju awon onigbagbo ododo (Olohun ki o yonu si) se fun awon ara Jerusalemu ni ti idabobo: o se adehun idabobo fun won lori emi won, lori dukia won, lori awon ile ijosin (soosi) won ati lori awon agbelebu won…. Ko si ijeni-nipa fun won lori esin won atipe ko si enikankan ti won yoo fi owo inira kan ninu won ….''
Nje itan omoniyan wa ri iru apejuwe abiyi, ti o duro lori deedee ati amojukuro (aanu) bayi ri lati odo olusegun si odo eniti won se logun? pelu pe o (Umar) ni ikapa o si wa ni ipo ki o pa won lase oun ti o ba fe ki o si fun won ni awon mojemu ti o ba wu u, sugbon o lo ilana sise deedee ati irorun (aanu) pelu won. Eleyi je oun pataki kan ti ntoka lori wipe ogun jija ninu esin Islam duro lori ibanilo niti omoniyan ti kii si se ti ojukokoro lori awon nkan aye.

Irorun Esin Islam Ni Abala Aforijin Ese Ati Amojukuro
Nitoripe omoniyan je eni ti o po ni asise ati ese yala laarin awon ati Oluwa won ni tabi laarin awon ati awon ti won jo nse ninu awujo. Eleyi si ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun wa nipa re ninu oro re ti o so bayi pe:
"كل بني آدم خطاء وخير الخطائين التوابون " أَخْرَجَهُ اَلتِّرْمِذِيُّ، وَابْنُ مَاجَهْ
'' gbogbo omoniyan ni alasise, (sugbon) eyi ti o loore julo ninu awon alasise naa ni awon ti o ma nronu piwada ''(At-tirmidhi ati Ibn Majah).
Awon ese wonyi ati iyapa Olohun ti omoniyan nse latari ogun lailai ati adehun tipetipe ti esu ti se pe oun yoo si omoniyan lona pelu itanje. Olohun ti ola Re ga so nipa adehun ti esu se lori omoniyan bayi pe
" قَالَ رَبِّ بِمَا أَغْوَيْتَنِي لَأُزَيِّنَنَّ لَهُمْ فِي الْأَرْضِ وَلَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ" الحجر39
'' Oun (Ibilisi) si sope: Oluwa mi, nitori sise ti o semi ni eni anu, dajudaju emi yoo se awon nkan buburu loso fun won lori ile atipe emi yoo so gbogbo won di eni anu '' Q15:39.
1- Ninu irorun ati irora esin Islam ni pe, dajudaju Olohun ma nse aforijin ese bi o tiwu ki eru mo paara re to (se ni asetunse) niwonba igba ti o ba ti nwa aforijin lo si odo Olohun. Olohun Alanu se eleyi nitoripe adamo omoniyan ni ki o da ese, awon ese wonyi si ni aforijin ati amojukuro niwon igba ti eru kobaye ti kogbo leni ti nwa aforijin lo si odo Oluwa re. Abu Saee'd Al-Khudri sope Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope
" قال: إِبْلِيسُ أي رَبِّ لاَ أَزَالُ أغوي بني آدَمَ ما دَامَتْ أَرْوَاحُهُمْ في أَجْسَادِهِمْ، قال: فقال الرَبُّ عز وجل:"لاَ أَزَالُ أَغْفِرُ لهم ما استغفروني" مسند الإمام أحمد صحيح الجامع 1650
'' Ibilisi sope: ire Oluwa mi, mi o ni yee tan awon omoniyan je niwonba igba ti emi ba si nbe lara won. O sope; Oluwa wa ti o je Abiyi Oba ti o gbongbon si dahun wipe: (emi naa) mi o ni yee se aforijin fun won niwonba igba ti won ba ti nwa mi ni alaforijin '' (Ahmad).
Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" وَالَّذِي نَفْسِي بيده لو لم تُذْنِبُوا لَذَهَبَ الله بِكُمْ وَلَجَاءَ بِقَوْمٍ يُذْنِبُونَ فَيَسْتَغْفِرُونَ اللَّهَ فَيَغْفِرُ لهم" (أحمد، ومسلم)
'' Mo fi eni ti emi mi nbe lowo re bura pe ti e ko ba mo d'ese ni Olohun o ba ti koyin kuro lori ile, ko ba si mu awon eniyan miran wa ti won yoo ma d'ese ti won yoo si ma wa Olohun ni alaforijin ti (Oun naa) yoo si ma forijin won '' (Muslim ati Ahmad).
2- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se ilekun ironupiwada ni oun ti o wa ni sisi fun musulumi ni gbogbo igba ati asiko. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" فَمَنْ تَابَ مِنْ بَعْدِ ظُلْمِهِ وَأَصْلَحَ فَإِنَّ اللَّهَ يَتُوبُ عَلَيْهِ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ"المائدة 39
'' Enikeni ti o ba ronupiwada (ti o pada sodo Olohun) leyin abosi re (ti o se) ti o wa se daadaa, dajudaju Olohun yoo gba ironupiwada re. Dajudaju Olohun ni Alaforijin Onike '' Q5:39.
 Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إن الله تعالى يبسط يده بالليل ليتوب مسيء النهار ويبسط يده بالنهار ليتوب مسيء الليل حتى تطلع الشمس من مغربها " مسلم
'' Dajudaju Olohun ma nte owo re kale ni ale lati gba ironupiwada olufosan sebaje, bakanaa Oma nte owo kale l'osan lati gba ironupiwada oluforu sebaje (yoo ma se bayi lojojumo) titi ti ooru yoo fi yo nibi ti nwo si '' (Muslim).
Ayafi awon aaye perete nikan ni ilekun gbigba ironupiwada ti le ti mo eru. Olohun ti ola Re ga nso bayi pe:
 " إِنَّمَا التَّوْبَةُ عَلَى اللَّهِ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السُّوءَ بِجَهَالَةٍ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِنْ قَرِيبٍ فَأُولَئِكَ يَتُوبُ اللَّهُ عَلَيْهِمْ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا (17) وَلَيْسَتِ التَّوْبَةُ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ حَتَّى إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ إِنِّي تُبْتُ الْآنَ وَلَا الَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمْ كُفَّارٌ..."
'' Igba ironupiwada ti Olohun ma ngba oun ni ti awon ti won fi alaimo se aburu, leyinnaa ti won ronupiwada laipe. Awon wonyi ni awon ti Olohun yoo gba ironupiwada won. Olohun si je Olumo Ologbon \\ Ko si igba ironupiwada fun awon ti won nse aburu titi ti iku fi de ba okookan won ti o wan wipe: Dajudaju emi ronupiwada nisisin yi, beeni ko si fun awon eni ti won ku si inu keferi sise. Awon wonyi awa ti pese iya oloro sile fun won '' Q4:17-18.
 Ilekun gbigba ironupiwada wa ni sisi fun awon erusin Olohun ayafi ni awon aaye meji kan ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) salaye ninu oro re pe:
" إن الله عز وجل يقبل توبة العبد ما لم يغرغر " الترمذي صحيح
'' Dajudaju Olohun Abiyi Oba ti O gbongbon yoo ma gba ironupiwada erusin re niwonba igba ti ko ba ti mo pokaka iku '' (At-tirmidhi).
Ati oro ti o so pe:
"من تاب قبل أن تطلع الشمس من مغربها تاب الله عليه " مسلم
'' Enikeni ti o ba ronupiwada siwaju ki oorun to o yo nibi ti o ti nwo Olohun yoo gba ironupiwada re " (Muslim).
3- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se ona lati ronupiwada ni oun ti o rorun pupo, o se ni nkan ti o wa laarin olujosin ati Oluwa re ti ko si ni bukata si alagata kankan laarin awon mejeeji, bakanna ko si ilekoko tabi inira kankan nibe, oun ti o wa nibe ni ki erusin Olohun gbe owo re soke ki o si se apatenujewo awon ese re fun Oluwa re, ki o si toro aforijin ati amojukuro lodo Re. Olohun ti ola re ga so bayi pe:
" وَمَنْ يَعْمَلْ سُوءًا أَوْ يَظْلِمْ نَفْسَهُ ثُمَّ يَسْتَغْفِرِ اللَّهَ يَجِدِ اللَّهَ غَفُورًا رَحِيمًا (110) "
'' Enikeni ti o ba se ise aburu tabi o se baosi emi ara re, leyinnaa ti o wa Olohun ni alaforijin, yoo ba Olohun ni Alaforijin Onike '' Q4:110.
4- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, aburu ti awon elese ba se, ti won wa ronupiwada lori re leni ti o je olododo ninu ironupiwada won, ti won si nbanuje lori awon oun ti o waye lowo won ni ese, ti won si ipinnu emi lati ma pada si idi ese naa mo, awon ese won wonyi yoo di daadaa fun won (ni akosile). Olohun ti ola Re ga so bayi pe
" وَالَّذِينَ لَا يَدْعُونَ مَعَ اللَّهِ إِلَهًا آخَرَ وَلَا يَقْتُلُونَ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللَّهُ إِلَّا بِالْحَقِّ وَلَا يَزْنُونَ وَمَنْ يَفْعَلْ ذَلِكَ يَلْقَ أَثَامًا (68) يُضَاعَفْ لَهُ الْعَذَابُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَيَخْلُدْ فِيهِ مُهَانًا (69) إِلَّا مَنْ تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ عَمَلًا صَالِحًا فَأُولَئِكَ يُبَدِّلُ اللَّهُ سَيِّئَاتِهِمْ حَسَنَاتٍ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا (70) "
'' Atipe awon ti won kii pe olohun miran pelu Olohun, won kii si pa emi ti Olohun se (pipa re) ni eewo afi pelu ododo (eto) won kii si se pansaga. Eniti o ba eyi nni yoo pade (idajo) ese (re) \\ A o se iya ni ilopo meji fun un ni ojo igbende yoo si gbere sinu re ni eni yepere \\ ayafi eniti o ba ronupiwada ti o si gbagbo ni ododo ti o si se ise rere, awon elewonyin ni Olohun yoo so ise buburu won di ise rere. Olohun je Alaforijin Alanu '' Q25:68-70.
 Ofin esin Islamba lakaye elese soro, o si wa iwosan fun idamudabo emi re pelu sisi ilekun ironupiwada sile fun un ki o le ba jawon nibi ese. Olohun wa ti ola Re ga ko mu enikankan ninu eda Re jakan kuro nibi riri aforijin, amojukoro, ati aanu lori ese ati asise re, bi o tiwu ki ese tabi asise naa tobi to. Olohun ti ola Re ga nso bayi pe:
" قُلْ يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ أَسْرَفُوا عَلَى أَنْفُسِهِمْ لَا تَقْنَطُوا مِنْ رَحْمَةِ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ جَمِيعًا إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ (53) "
'' Sope: Eyin erusin Mi, ti e ti d'ese bo emi yin (lorun), e ma se so ireti nu nipa ike Olohun, dajudaju Olohun ma nse aforijin gbogbo ese patapata. Dajudaju Oun ni Alaforijin Alaanu Q39:53.
Awon eleyi nii se pelu iwo ati eto Olohun sugbon awon nkan ti o nii se pelu iwo ati eto omoniyan, oranyan ni ki a da iwo tabi eto naa pada fun eni ti o ni, ki a si toro amojukuro lowo won lori eto ati iwo won ti a mu.
5- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o ma nsan esan daadaa lori aniyan daradara ti eniyan ba ni koda ki o ma pada fi sise. Ti o ba ni ipinnu lati se daadaa sugbon ko pada se e, won yoo ko sile fun pe o se daadaa kan. Koda oro a tun ma koja bayi ni igba miran, ti musulumi ba pinnu lati se aburu ti ko wa see mo latara iberu iya Olohun, Olohun yoo tun san ni esan daadaa lori re, nitoripe o fi oun ti o ti ni ipinnu lori re nitori iberu Olohun. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope: Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
"إذا أراد عبدي أن يعمل سيئة فلا تكتبوها عليه حتى يعملها فإن عملها فاكتبوها بمثلها وإن تركها من أجلي فاكتبوها له حسنة وإذا أراد أن يعمل حسنة فلم يعملها فاكتبوها له حسنة فإن عملها فاكتبوها له بعشر أمثالها إلى سبعمائة ضعف "
'' Nigba ti erusin Mi ba gbero lati se aburu, e ko gbodo koo sile fun titi ti yoo fi se e, ti o ba wa ti se e ko sile ni deedee odiwon re (oun ti o se), sugbon ti o ba fii sile (ti ko see) nitori Mi, e fi ko daadaa kan sile fun, nigba ti o ba si gbero lati se daadaa sugbon ti ko si se, e fi ko daadaa kan sile fun un, sugbon ti o ba wa see, e ko sile fun ni ilopo mewa re titi de ilopo re lona ogorun meje ''
5- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, ko se ese musulumi ni adina fun nibi riri ike ati aanu Olohun, bikosepe o se ni oun ti yoo ma rankan ki ese re po si (ni ojo igbende) fun oun ti yoo ri ni ike ati aanu Olohun pelu aforijin Re, nigba ti won ba fi iwe ise re han an. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إني لأعلم آخر أهل الجنة دخولاً الجنة وآخرَ أهل النار خروجاً منها رجلٌ يؤتى به يوم القيامة فيقال اعرِضوا عليه صغار ذنوبه وارفعوا عنه كبارها فتعرض عليه صغار ذنوبه فيقال عمِلت يوم كذا وكذا كذا وكذا وعملت يوم كذا وكذا كذا وكذا فيقول نعم لا يستطع أن ينكر وهو مشفِق(خائف) في كبار ذنوبه أن تعرض عليه فيقال له فإن لك مكان كل سيئةٍ حسنة فيقول يا رب قد عملت أشياء لا أراها هاهنا" فلقد رأيت رسول الله صلى الله عليه وسلم ضحك حتى بدت نواجذه.) رَوَاهُ مُسْلِمٌ
'' Dajudaju mo mo eniti yoo wo ogba idera kanyin, ti yoo si jade kanyin ninu ina; arakunrin kan ti won yoo mu wa ni ojo igbende, won yoo so pe: e fi awon ese keekeekee ti o wa ninu ise re han an ki e si mu awon iya ese kuro fun un, won a wa fi awon ese re keekeekee han an, won a wa so fun pe; o se bayi bayi ni ojo bayi, o se bayi bayi no jo bayi, o se bayi bayi ni ojo bayi, yoo si mo dahun wipe beeni ko ni le so pe ko ri bee, nigbati o jepe o kuku npaya lori awon ese nla nla wipe ki won ma fi han oun, won a wa so fun un pe: bayi gbogbo ikookan ninu awon ese wonyini won yoo fi san o ni esan daadaa! yoo wa sope: ire Oluwa mi, mo da awon ese kan ti won ko ko sibi '' mo ri Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti on rerin titi ti awon eyin ogan re fi han sita '' (Muslim).
6- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, dajudaju Olohun je Alagbamora lori eniti o ba yapa Re ninu awon erusin Re ti o si tun se aigbagbo si I. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" وَلَوْ يُؤَاخِذُ اللَّهُ النَّاسَ بِمَا كَسَبُوا مَا تَرَكَ عَلَى ظَهْرِهَا مِنْ دَابَّةٍ وَلَكِنْ يُؤَخِّرُهُمْ إِلَى أَجَلٍ مُسَمًّى فَإِذَا جَاءَ أَجَلُهُمْ فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِعِبَادِهِ بَصِيرًا" فاطر45
'' Bi o ba sepe Olohun yoo mu awon eniyan fun ise ese won ni, ko ni seku eda kankan lori ile. Sugbon O nlo won lara di akoko kan ti a so; nitorinaa ti akoko naa ba de, dajudaju Olohun yoo je Oluriran nipa awon erusin Re '' Q35:45.

Irorun Ati Aanu Esin Islam Nibi Gbigbe Awon Oun Ipa Ese Re Kale
Ninu irorun ati aanu esin Islam ni pe, o gbe awon ise ijosin kan kale ti o je pe yato si pe won je ise ti o ni esan ninu won tun je ipare-ese, eleyi je ika ati aanu lati odo Olohun fun awon erusin Re, o si je ifini lokanbale bale fun won ati ona-abayo ninu ese won ti o po. Ninu awon nkan wonyi naa ni:
1- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni pe, o se sise ijosin oranyan ni ipa esere yato si pe o je ise ti o ni esan pupo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
« الصلوات الخمس والجمعة إلى الجمعة ورمضان إلى رمضان مكفرات ما بينهن إذا اجتنبت الكبائر » رواه مسلم.
'' (Ikookan) Iru wakati marun ojumo (si ekeji), ati irun Jimoh kan si Jimoh keji, ati awe Ramadana kan si Ramadana keji, won je ipa esere fun oun ti nbe laarin ara won nigba ti a ba jinna si iya ese '' (Muslim).
2- Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" تابعوا بين الحج والعمرة فإنهما ينفيان الفقر والذنوب كما ينفي الكير خبث الحديد والذهب والفضة وليس للحجة المبرورة ثواب دون الجنة" صحيح - "الصحيحة" (1200)
'' E ma fi Hajji ati Umura tele ara won, nitoripe awon mejeeji mo npa osi ati ese re gegebi ina se mo npa didogun irin, wura ati fadaka re. ko si esan kankan fun ise Hajji ti o je atewogba ti o kere si ogba idera (Al-Jannah) '' (Al Bukhari).
3- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se jijinna si awon ese nla ni okunfa lati ri aforijin lori awon ese keekeekee, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
" إِنْ تَجْتَنِبُوا كَبَائِرَ مَا تُنْهَوْنَ عَنْهُ نُكَفِّرْ عَنْكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَنُدْخِلْكُمْ مُدْخَلًا كَرِيمًا" النساء 31
'' Ti e ba file jinna si awon ese nla nla ti won ko fun yin, A o se ipare awon aburu yin (ese keekeekee) A o si mu yin wo ibuwo alaponle '' Q4:31.
4- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se fifonrere salamo (ikini pelu gbolohun "as-salam alaykum") ati bibo ara eni lowo ni ipa esere laarin awon musulumi. Hudhayfa (Olohun ki o yonu si) sope; Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إن المسلم إذا صافح أخاه تحاتتخطاياهما كما يتحت ورق الشجر " رواه البزار وصححه الألباني
'' Dajudaju nigba ti musulumi b abo omo-iya (musulumi) re lowo ese awon mejeeji yoo ma re danu gegebi ewe se ma nre danu lara igi '' (Al-bazar).
5- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se eyikeyi ti o ba de ba erusin Olohun ninu awon aisan, adanwo tabi ibanuje ni oun ti Olohun fi ma npa awon ese ati asise erusin Re. Abu Saee'd Al-Khudri (Olohun ki o yonu si) sope; Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" ما من شَيْءٍ يُصِيبُ الْمُؤْمِنَ من نَصَبٍ ولا حَزَنٍ ولا وَصَبٍ حتى الْهَمُّ يَهُمُّهُ إلا يُكَفِّرُ الله بِهِ عنه سَيِّئَاتِهِ" رَوَاهُ مُسْلِمٌ
'' ko si oun ti yoo sele si onigbagbo ododo ninu inira, tabi ibanuje, tabi aisan olojopipe titi ti o fi d'ori iponju ti o ba de ba ayafi ki Olohun fi pa awon asise re re '' (Muslim).
Bakan naa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun so pe:
" ما من مُصِيبَةٍ تُصِيبُ الْمُسْلِمَ إلا كَفَّرَ الله بها عنه حتى الشَّوْكَةِ يُشَاكُهَا"متفق عليه
'' Ko si adanwo kan ti yoo de ba onigbagbo ododo ayafi ki Olohun fi pa ese re re, koda ti o fi dori egun ti o ba gun un '' (Al Bukari ati Muslim).
6- Bakan naaninu irorun esin Islam tun ni pe, o se imora ni ipa ese re. Abu Saee'd Al-Khudri sope; Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" ألا أدلكم على ما يكفر الله به الخطايا ويزيد في الحسنات؟ "قالوا: بلى يا رسول الله قال:" إسباغ الوضوء في المكاره وانتظار الصلاة بعد الصلاة ما منكم من رجل يخرج من بيته فيصلي مع الامام ثم يجلس ينتظر الصلاة الأخرى إلا والملائكة تقول اللهم اغفر له اللهم ارحمه" رواه ابن ماجه وابن خزيمة وابن حبان في صحيحه واللفظ له والدارمي في مسنده وصححه الألباني
'' Se ki njuyin niwe oun ti o Olohun ma nfi se ipare awon asise re ti o si ma nse alekun daadaa? won dahun wipe: beeni ire ojise olohun, o si dahun wipe: sise asepe aluwala nigba ti ko rorun, ati mimo reti irun kan leyin irun, ko si enikankan ti yoo jade nile re ninu yin lo si mosalasi ti yoo si kirun pelu imam leyin naa ti o wa joko ti o nreti irun miran ayafi ki awon molaika ma so pe " Olohun forijin, Olohun ke '' (Ibn Majah ati Ibn Khuzaymo).
7- Bakan naa ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se ise kekere ninu iranti Olohun ni oun ti o se deedee inawo si oju ona Olohun ninu gbogbo oniranran daadaa. Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) sope: awon talaka kan wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) won si sope:
" ذَهَبَ أَهْلُ الدُّثُورِ (أي أهل الأموال الكثيرة) من الْأَمْوَالِ بِالدَّرَجَاتِ الْعُلَا وَالنَّعِيمِ الْمُقِيمِ يُصَلُّونَ كما نُصَلِّي وَيَصُومُونَ كما نَصُومُ وَلَهُمْ فَضْلٌ من أَمْوَالٍ يَحُجُّونَ بها وَيَعْتَمِرُونَ وَيُجَاهِدُونَ وَيَتَصَدَّقُونَ قال ألا أُحَدِّثُكُمْ بأمر إن أَخَذْتُمْ به أَدْرَكْتُمْ من سَبَقَكُمْ ولم يُدْرِكْكُمْ أَحَدٌ بَعْدَكُمْ وَكُنْتُمْ خَيْرَ من أَنْتُمْ بين ظَهْرَانَيْهِ (أي كنتم خير ممن أنتم بينهم) إلا من عَمِلَ مثله تُسَبِّحُونَ وَتَحْمَدُونَ وَتُكَبِّرُونَ خَلْفَ كل صَلَاةٍ ثَلَاثًا وَثَلَاثِينَ فَاخْتَلَفْنَا بَيْنَنَا فقال بَعْضُنَا نُسَبِّحُ ثَلَاثًا وَثَلَاثِينَ وَنَحْمَدُ ثَلَاثًا وَثَلَاثِينَ وَنُكَبِّرُ أَرْبَعًا وَثَلَاثِينَ فَرَجَعْتُ إليه فقال تَقُولُ سُبْحَانَ اللَّهِ وَالْحَمْدُ لِلَّهِ وَاللَّهُ أَكْبَرُ حتى يَكُونَ مِنْهُنَّ كُلِّهِنَّ ثَلَاثًا وَثَلَاثِينَ)رواه مسلم
'' awon oloro (olowo) repete ti ko gbogbo ipo giga ati idera lo tan, won nkirun bi awa naa se nkirun won si ngba awe bi awa naa se ngba awe, won si tun ni asekubo ninu owo ti won si fi nse ise Hajji ati Umura, won njagun si oju ona Olohun, won si nse itore aanu. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe: se ki nso nkankan tojepe ti e ba nse e eyin yoo le awon ti o siwaju yin ba, enikankan ninu awon to nbo leyin yin ko si ni leyin ba yin, eyin yoo wa je eniti o loore ju awon ti o siwaju yin ati awon ti o wa leyin yin lo, ayafi eniti o ba se iru onu ti e se; e maa se afomo fun Olohun (subhanallah) ki e si maa dupe fun un (al-hamdulillah) ki e si ma se gbigbe tobi fun un (Allahu akbar) ni eyin irun kookan ni igba meta-le-logbon. Iyapaenu sele laarin wa; awon kan sope oun ti o wi ni pe; ki a se afomo ni igba metadelogbon ki a si se idupe ni igba metalelogbon ki a si se gbigbe tobi ni igba metalelogbon. Mo wa pada si odo re (lati beere), o wa sope; ma sope: Subhanallah wal-hamdulillah wallahu akbar titi ti gbogbo re yoo fi pe metalelogbon lapapo '' (Muslim).
 7- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se ki eniyan po ni daadaa sise ni oun ti ma nse apare ese. Muaa'dh (Olohun ki o yonu si) sope oun sope ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so asotele fun mi? o si dahun wipe:
" اتَّقِ اللَّهَ حَيْثُمَا كُنْتَ أو أَيْنَمَا كُنْتَ " قال: زدني، قال:"اتبع السَّيِّئَةَ الْحَسَنَةَ تمسحها " قال: زدني، قال: " خَالِقِ الناس بِخُلُقٍ حَسَنٍ "احمد صحيح
'' beru Olohun ni aayekaye ti o ba wa. O sope: se alekun re, o si tun dahun wipe: si ma fi daadaa tele aburu (ti o ba se) nitoripe yoo paree. O si tun sope: se alekun re, oun naa si dahun wipe: ki o si ma awon eniyan lo pelu iwa ti o dara '' (Ahmad).
8- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se sise awon ijosin ni oun ti o ma nse apare awon ese keekeekee, eri eleyi ni oro ti o wa lati odo Abu Umamah (Olohun ki o yonu si) wipe arakunrin kan wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) o si sope: ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) mo koja enu-aala (Olohun) (ese to ye ki won faa leti le lori) waa se idajo lemi lori!!! Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun bayi pe:
"توضأت حين أقبلت ؟ " قال: نعم، قال: " هل صليت معنا حين صلينا ؟ " قال: نعم، قال: " اذهب فإن الله تعالى قد عفا عنك " مُتَّفَقٌ عَلَيهِ.
'' nje o se aluwala nigb ti o nbo bi? o dahun wipe: beeni, o tun beere wipe: nje o kirun pelu wa nigba ti a nkirun bi? o tun dahun wipe: beeni, o wa so bayi pe: maa lo nitoripe dajudaju Olohun ti se amojukuro fun o '' (Al Bukhari).

Irorun Ati Aanu Esin Islam Pelu Gbigbe Awon Itanran Awon Ese Kale
 Ninu irorun ati irora esin Islam ni pe, o se agbekale awon itanran orisirisi fun awon erusin Olohun nigba ti won ba se awon oun ti ko leto yala nibi iwo Olohun tabi iwo awon eniyan akegbe won, lati le je okunfa amojukuro ati aforijin fun won lori awon ese ti won da. Awon itanran wonyi wa lati pa ibanuje ti o wa pelu musulumi latara ese ti o da re leyin ti o ba ti san awon itaran naa, nitori ki o ma ba mo semi ninu aibale emi latari ese ti o da. Awon wonyi si ni die ninu awon apejuwe irorun ati irora ti o wa nibi awon itanran naa:
1- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni abala pipaniyan ni ti asise ni pe, o gbe itanran kale, eyi ti Olohun Onibukun Oba ti ola Re ga salaye ninu oro Re bayi pe:
" وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ أَنْ يَقْتُلَ مُؤْمِنًا إِلَّا خَطَأً وَمَنْ قَتَلَ مُؤْمِنًا خَطَأً فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ وَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَى أَهْلِهِ إِلَّا أَنْ يَصَّدَّقُوا فَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ عَدُوٍّ لَكُمْ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ وَإِنْ كَانَ مِنْ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ فَدِيَةٌ مُسَلَّمَةٌ إِلَى أَهْلِهِ وَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُؤْمِنَةٍ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ شَهْرَيْنِ مُتَتَابِعَيْنِ تَوْبَةً مِنَ اللَّهِ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا" النساء 92
'' Ko si to si onigbagbo ododo kan, ki o pa onigbagbo ododo kan, ayafi ti o ba se eesi, eniti o ba si pa onigbagbo ododo ni ti eesi, ki o so eru kan onigbagbo ododo di omoluwabi ati ki o san owo emi fun awon eniyan oku naa. Ayafi ti won ba fi tore (fun un). Ti o ba je ninu awon eniyan kan ti won je ota fun yin, ti o si je onigbagbo ododo, siso eru kan ti o gbagbo di omoluwabi (ni oranyan). Ti o ba awon ijo ti adehun nbe laarin eyin pelu won ni, sisa owo emi fun awon eni re (di oranyan), ati siso eru ti o nigbagbo di omoluwabi di ominira; eni ti ko ba si rieru ti o ni igbagbo, nigbanaa ki o gba awe osu meji tele ara won (di oranyan fun un). O je ironupiwada lati odo Olohun wa, atipe Olohun ni Onimimo Ologbon '' Q4:92.
2- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni abala ki oko fi eyin iyawo re we eyin iya re ni pe, o gbe itanran kale fun un eyi ti Oluwa wa Onibukun Oba ti ola Re ga salaye ninu oro Re bayi pe
" وَالَّذِينَ يُظَاهِرُونَ مِنْ نِسَائِهِمْ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا قَالُوا فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَتَمَاسَّا ذَلِكُمْ تُوعَظُونَ بِهِ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ" المجادلة 3
'' Atipe awon ti won ba fi eyin iyawo won we eyi iya won, leyinnaa ti won wa fe seri nipa oun ti won so nigbanaa won yoo so eru kan di ominira siwaju ki won to le fowo kan ara won (oko ati iyawo). Awon wonyi ni a se kilokilo fun yin nipa re, Olohun je Eni ti o mo nipa oun ti e nse nise '' Q58:3.
3-Ninu irorun ati aanu esin Islam ni abala ibura lori ileri ni pe, o gbe itanran kale fun un, eyi ti Olohun Oba ti o mo tonitoni ti ola Re si ga salaye ninu oro Re bayi pe:
" لَا يُؤَاخِذُكُمُ اللَّهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَكِنْ يُؤَاخِذُكُمْ بِما عَقَّدْتُمُ الْأَيْمَانَ فَكَفَّارَتُهُ إِطْعَامُ عَشَرَةِ مَسَاكِينَ مِنْ أَوْسَطِ مَا تُطْعِمُونَ أَهْلِيكُمْ أَوْ كِسْوَتُهُمْ أَوْ تَحْرِيرُ رَقَبَةٍ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ ذَلِكَ كَفَّارَةُ أَيْمَانِكُمْ إِذَا حَلَفْتُمْ وَاحْفَظُوا أَيْمَانَكُمْ كَذَلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ" المائدة 89
'' Olohun ki yoo mu yin ba fun ara ti e bu niti ere, sugbon Oun yoo mu yin fun ti e finufidi bu, nitorinaa itanran re ni bibo talika mewa (ni aboyo) ninu ounje ti o dara ju ti e nfun awon eniyan yin, tabi wiwo won laso tabi ki e so eru kan di omo, eni ti ko ba ri (nkankan ninu awon wonyi) awe gbigba ojo meta (lokan), eyi ni itanran ibura yin nigba ti e ba ti bura, e maa mu ibura yin se, bayi ni Olohun nse alaye awon oro Re ki e le ma dupe '' Q5:89.
4- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni abala itanran tun ni pe, o see ni oun ti won ma nyoda (ti sise re yoo kuro ni oranyan) fun omoniyan nigba ti ko ba ni ikapa lati se e, yala eyi ti o je afowose ni tabi eyi ti o je afarase. Eri eleyi ni itan Sahabe kan ti o wa ba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o si sope: ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), mo ti parun, ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si da lohun wipe:
" ما لك " قال: وقعت على امرأتي وأنا صائم فقال رسول الله صلى الله عليه وسلم:" هل تجد رقبة تعتقها؟ " قال: لا قال: "فهل تستطيع أن تصوم شهرين متتابعين؟ " قال: لا فقال: " فهل تجد إطعام ستين مسكينا؟ " قال: لا قال: فمكث النبي صلى الله عليه وسلم فبينا نحن على ذلك أتي النبي صلى الله عليه وسلم بعرق فيه تمر والعرق المكتل قال: " أين السائل؟ " فقال: أنا قال: " خذ هذا فتصدق به " فقال الرجل: أعلى أفقر مني يا رسول الله؟ فوالله ما بين لابتيها أهل بيت أفقر من أهل بيتي فضحك النبيحتى بدت أنيابه ثم قال: " أطعمه أهلك "
''ki lo se o? o si dahun wipe: mo ba iyawo mi lopo losan awe, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe: nje o nikapa lati so eru di omoluwabi? o si dahun wipe: rara, o tun beere wipe: nje o nikapa lati gba awe osu meji tele ara won? o tun dahun pe: rara, o tun bi leere wipe: nje o nikapa lati bo alaini ogota? o si tun dahun wipe rara, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa bee titi, laarin igba yi ni won gbe apere kan wa fun un ti o si kun fun eso tamuru, apere naa je eyi ti won latara igi ope (tamuru), o wa beere pe: eni ti nbeere ibeere da? o si dahun wipe: emi ni, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si so fun pe: gbe apere yi ki o si lo fi tore, arakunrin ba dahun wipe: nje enikan nbe ti o tosi jumi lo ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)? mo fi Olohun bura wipe ko si ile kan ti o tosi ju ile mi lo latoke-dele ilu Madinah yi, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba bu serin titi ti eyin ogan re fi han sita, o si so bayi pe: lo fun awon ile re je''.

Irorun Ati Aanu Esin Islam Ni Abala Ki Daadaa Erusin Olohun Maa Tesiwaju
 1- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni pe, o se musulumi ni eni ti yoo ma gba esan ise daadaa eyi ti ko se latara ojukokoro re lati se daadaa naa. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so ninu oro re bayi pe:
" من دعا إلى هدى كان له من الأجر مثل أجور من اتبعه لا ينقص ذلك من أجورهم شيئاً ومن دعا إلى ضلالة كان عليه من الأثم مثل آثام من أتبعه لا ينقص ذلك من آثامهم شيئاً "
'' Enikeni ti o ba pepe lo sibi onamo, yoo gba esan ti o da gegebi esan gbogbo eni ti o tele e (lori re) ti ko si ni dinku ninu esan won rara, bakan naa enikeni ti ba pepe lo sibi ona anu, yoo ma gba ese ti o da gegebi ese gbogbo eni ti o tele (lori re) ti ko si ni fa adinku rara si ese won"
Eleyi ni o ma nje ki musulumi ma se ojukokoro ti o lagbara lori titun awujo re se pelu sise awon ise daadaa ninu awujo, tabi ki o ran ise naa lowo (pelu owo tabi ara), ti yoo si tun ma pepe si daadaa naa, bakan naa yoo ma gbogun ti ibaje ti yoo si ma se kilokilo fun awon eniyan lori re, ko ni ma fan ibaje ka tabi ki o polongo re laarin awujo, gbogbo eleyi lati je ki iwe ise re mo tonitoni kuro nibi ise aburu ati ibaje. Pelu bayi ni yoo si fi ma se afomo emi ara re ati awujo re.
2- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, o se ki a reni (fun ni ni eko) lona daadaa (lori ti Olohun ati igbesi aye), ati ki a fon (ko awon eniyan ni) imo ka laarin awujo omoniyan ni oun ti omoniyan yoo ma gba esan daadaa le lori yala nigba ti o ba nbe laye ni tabi nigba ti o ba ti ku. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" إذا مات الإنسان انقطع عنه عمله إلا من ثلاثة إلا من صدقة جارية أو علم ينتفع به أو ولد صالح يدعو له"
'' Nigba ti omoniyan ba ti ku gbogbo ise re ni o ti ge ayafi meta kan; ayafi itore aanu ti nlo gbere, tabi imo ti awon eniyan nse anfaani latara re, tabi omo rere (ti o fi sile) ti wa nse adua fun un ''

Irorun Ati Aanu Esin Islam Ni Abala Igbadun Omoniyan
 Dajudaju ninu irorun ati irora, aanu ati inife daadaa esin Islam fun awon musulumi ni pe, o so awon isesi won ati igbadun won di ise rere ti won yoo ma gba esan le lori nigba ti aniyan ati erongba won ba dara lori re. Ninu apejuwe awon nkan wonyi ni:
1- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni pe, ti musulumi ba je igbadun pelu sise asepo (ibalopo laarin okunrin ati obinrin) ni ona eto pelu iyawo re pelu aniyan siso emi ara re ati enikeji re nibi isekuse (agbere), isesi re yii yoo wa ni ipo ijosin ti yoo gba esan le lori. Abu Dharr (Olohun ki o yonu si) sope awon eniyan kan ninu awon omoleyin Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa si odo re, won si sope:
" ذَهَبَ أَهْلُ الدُّثُورِ بِالْأُجُورِ يُصَلُّونَ كما نُصَلِّي وَيَصُومُونَ كما نَصُومُ وَيَتَصَدَّقُونَ بِفُضُولِ أَمْوَالِهِمْ؟ قال:" أَوَ ليس قد جَعَلَ الله لَكُمْ ما تَصَّدَّقُونَ إِنَّ بِكُلِّ تَسْبِيحَةٍ صَدَقَةً وَكُلِّ تَكْبِيرَةٍ صَدَقَةً وَكُلِّ تَحْمِيدَةٍ صَدَقَةً وَكُلِّ تَهْلِيلَةٍ صَدَقَةً وَأَمْرٌ بِالْمَعْرُوفِ صَدَقَةٌ ونهى عن مُنْكَرٍ صَدَقَةٌ وفي بُضْعِ أَحَدِكُمْ صَدَقَةٌ" قالوا يا رَسُولَ اللَّهِ: أَيَأتِي أَحَدُنَا شَهْوَتَهُ وَيَكُونُ له فيها أَجْرٌ؟ قال:" أَرَأَيْتُمْ لو وَضَعَهَا في حَرَامٍ أَكَانَ عليه فيها وِزْرٌ فَكَذَلِكَ إذا وَضَعَهَا في الْحَلَالِ كان له أَجْرًا "
''ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), awon olowo repete ti ko esan lo tan; won nkirun gegebi a se nkirun, won gba awe gegebi ase ngba awe, won si tun nse itore aanu ninu eyi ti o ba seku ninu owo won? o si wi bayi pe: se Olohun ko wa ti se fun yin ni bi awon oun ti eyin naa o fi ma se itore aanu; dajudaju gbogbo isafomo kookan (Subhanallah) itore aanu ni o je (fun yin), gbogbo siso pe Olohun tobi (Allahu akbar) kookan itore aanu lo je (fun yin), gbogbo idupe fun Olohun (Alhamdulillah) kookan itore aanu loje (fun yin), gbogbo siso pe ko si olohun kan ti o leto si ijosin ni ododo ayafi Olohun (La ilaha illa Allah) kookan itore aanu ni o je (fun yin), ipase daadaa itore aanu loje (fun yin), iko ibaje itore aanu ni o je (fun yin), bakan naa ibalopo enikookan (pelu iyawo re) yin itore aanu ni o je (fun yin),'' won si dahun wipe: ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), nje enikan ninu wa yoo wa maa je igbadun (ibalopo pelu iyawo re) ti yoo si tun maa gbesan lori re bi? o si dawon lohun pe: e woye si ki o jepe ona aito ni o gba se, se yoo gbese lori re bi? gege bee naa ni ti o ba se ni ona eto yoo gba esan daadaa ''
2- Ninu irorun ati aanu esin Islam tun ni pe, awon oun ti eniyan ma nse gegebi isesi lasan ma npada wa ni ipo ijosin eyi ti yoo gba esan daadaa le lori nigba ti aniyan daadaa ati erongba ti o mo ba ti siwaju. Ounje jije ati omi mimu fun apere; ti omoniyan ba ni aniyan pe oun fe fi so ara oun pelu okun ati agbara re lati le wa ije ati imu ni ona ti o leto ati lati le pe ojuse eyi ti Olohun se ni oranyan le lori nipa gbigbo bukata awon ara ile re ati awon ti nbe ni abe ikapani re ati lati ran awon omo iya re lowo, ki o si tun fi le ni okun lati se ijosin fun Olohun, yoo gba esan lori re. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:
" إذا أنفق الرجل على أهله يحتسبها فهو له صدقة "
'' Nigba ti baale ile ba na owo le awon ara ile re lori ti o si nrankan esan lodo Olohun, itore aanu ni yoo je fun un ''
Gbogbo eyikeyi ise ti musulumi ba se ti aniyan ati erongba re si dara lori re ni yoo wa ni ipo itore aanu fun un, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" على كل مُسْلِمٍ صَدَقَةٌ فَقَالُوا يا نَبِيَّ اللَّهِ فَمَنْ لم يَجِدْ قال يَعْمَلُ بيده فَيَنْفَعُ نَفْسَهُ وَيَتَصَدَّقُ قالوا فَإِنْ لم يَجِدْ قال يُعِينُ ذَا الْحَاجَةِ الْمَلْهُوفَ قالوا فَإِنْ لم يَجِدْ قال فَلْيَعْمَلْ بِالْمَعْرُوفِ وَلْيُمْسِكْ عن الشَّرِّ فَإِنَّهَا له صَدَقَةٌ" البخاري
'' Gbogbo musulumi kookan ni itore aanu je oranyan fun. Won wa sope: ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) eni ti ko ba ni nko? o si dahun wipe: ki o lo fi owo re sise, ki o se ara re ni anfaani leyin naa ki o se itore aanu. Won tun beere pe: ti ko tun ni nko? o si da won lohun wipe:ki o ran oni bukata ti nwa iranlowo. Won tun sope: ti ko ba tun ri nko? o si dahun wipe: ki o ya maa se daadaa ki o si jinna si aburu (eleyi naa) itore aanu loje '' (Al Bukhari).

Irorun Ati Aanu Esin Islam Ni Abala Ireni
Dajudaju ilana ti esin Islam gbe kale nibi ire-omo ati ikoni-leko je eyi ti o duro lori irora ati pelepele eyi ti o jinna si ilekoko ati ifunlemo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)
" إن الله لم يبعثني معنّتاً ولامُتعنّتناً، ولكن بعثني مُعلماً وميسراً "
'' Olohun ko gbe mi dide ni eni ti yoo ma ko awon eniyan sinu inira pelu sise ni oranyan fun won oun ti yoo ko inira ba won, ko si se mi ni olulekoko ati olujeni-npa, sugbon o gbe mi dide ni olukoni oluse pelepele (irorun) ''
1- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni abala igbani nimoran ni pe, o je ilana Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) eyi ti o duro lori nini ife daadaa, pelepele ati irora sise pelu pipile ife nibi ibeere, eyi ti o lo pelu odomode-kunrin ti o fe lati maa se agbere ti o si fe ki Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) yonda fun oun, ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si so fun bayi pe:
" أتحبه لأمك ؟ قال: لا والله، جعلني الله فداك، قال: ولا الناس يحبونه لأمهاتهم، قـال: أفتحبه لابنتك ؟ قال: لا والله يا رسول الله، جعلني الله فداك، قال: ولا الناس يحبونه لبناتهم، قال: أتحبه لأختك ؟ قال: لا والله جعلني الله فداك، قـال: ولا الناس يحبونه لأخواتهم، قال: أفتحبه لعمتك ؟ قال: لا والله جعلني الله فداك، قال: ولا الناس يحبونه لعماتهم، أفتحبه لخالتك ؟ قال: لا والله جعلني الله فداك ولا النـاس يحبـونه لخالاتـهم، قال: فوضع يـده علـيه وقـال: " اللهم اغفر له ذنبه، وطهّر قلبه وحصّن فرجه " صحيح الصَّحِيحَة: 370, وقال الأرنؤوط: إسناده صحيح.
'' nje o fe ki won se e pelu iya re bi? o dahun wipe: rara mo fi Olohun bura, ki Olohun o fi mi we (se idabobo) fun o. O si da lohun wipe: awon eniyan yoku naa ko ni fe re fun awon iya ti won naa. O tun bi leere wipe: nje o fe fun omo re lobinrin bi? o si dahun wipe: rara ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) mo fi Olohun bura ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki Olohun ki o fi mi we fun o. O si da lohun wipe: awon eniyan yoku naa ko ni fe re fun awon omo won naa. O tun bi leere wipe: nje o fe fun omo iya re lobinrin bi? o si dahun wipe: rara ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki Olohun o fi mi we fun o. O si da lohun wipe: awon eniyan yoku naa ko ni fe re fun awon omo iya won lobinrin.O tun beere wipe: nje o fe fun egbon abi aburo baba re lobinrin? o si dahun wipe: rara ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki Olohun o fi mi we fun o. O si da lohun wipe: awon eniyan yoku naa ko ni fe re fun awon egbon abi aburo baba won lobinrin. O tun beere wipe: nje o fe fun egbon abi aburo mama re lobinrin bi? o si dahun wipe: rara ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki Olohun o fi mi we fun o. O si da lohun wipe: awon eniyan yoku naa ko ni fe re fun awon egbon abi aburo mama won lobinrin. O sope; leyin naa ni o wa gbe owo re le ni aya ti o si so bayi pe: ire Olohun fori ese re jin in, ki o si ba mo emi (kuro nibi irokuro ati ifekufe) re, ki o si ba so abe re (kuro nibi isekuse) '' (At-tirmidhi).
2- Ninu irorun ati aanu esin Islam ni abala ikoni leko ni pe, o gbe ilana ti o rorun kale nibi kiko awon musulumi ni eko. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fi ilana ti o rorun pupo sile fun awon ti nbo leyin re latara itan re pelu okunrin larubawa oko eyi ti o wo mosalasi ti o si to sibe, awon omoleyin Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si jagbe mo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si so fun won pe:
" لا تزرموه "ثم دعاه فقال: " إن هذه المساجد لا تصلح لشيء من القذر والخلاء وكما قال رسول الله صلى الله عليه وسلم إنما هي لقراءة القرآن أو ذكر الله "ثم دعا بدلو من ماء فصبه عليه. متفق عليه
'' (e fi sile) e ma da ito mo nidi. Leyin naa ni o pee ti o si so fun pe: dajudaju awon mosalasi ko si fun nkan ninu egbin ati ito pelu igbe, atipe gegebi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se so pe: dajudaju oun ti a o wa fun ni kika Al-Kurani tabi iranti Olohun '' leyin naa ni o beere fun doro omi kan ti o si da le lori '' (Al Bukari ati Muslim).
Dajudaju eleyi ni irorun irora ati pelepele Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), ko fi iya je odomokunrin naa beesi ni ko le koko moo, pelu pe ese kan ninu awon ese nla ninu esin Islam ni odokunrin naa da. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ko le koko mo arakunrin larubawa oko alaimokan yi ti o to sinu mosalasi re (ike ati ola Olohun ki o ma ba) eyi ti o je aaye ti o lola julo lori ile, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se eleyi lati salaye ilana eyi ti o fe ki awa omoleyin re ma lo leyin re nibi kiko awon eniyan leko ati nibi igbani niyanju ati ireni.


NI IPARI
Ni aarin kika iwe yi yoo ti han si o gbangba gbangba ikolekan esin Islam nibi sise irorun ati irora pelu pipepe lo sibe, nitori sise daradara si awon eniyan ati ima tujuka pelu won, ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se so ninu oro re bayi pe:
"لَا تَحْقِرَنَّ من الْمَعْرُوفِ شيئا وَلَوْ أَنْ تَلْقَى أَخَاكَ بِوَجْهٍ طَلْقٍ" صحيح. رواه مسلم
'' Mase foju kere eyikeyi ninu daradara (ise rere), koda bi ose ki o pade omo iya re pelu oju tutu (titujuka) '' (Muslim).
 Bakan naa nitori pipepe lo sibi inife daadaa fun awon eniyan ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se so ninu oro re fun wa pe:
" أَحِبَّ لِلنَّاسِ ما تُحِبُّ لِنَفْسِكَ " خرَّجه الترمذي وابن ماجه
'' Mo fe fun awon eniyan oun ti o nfe fun emi ara re '' (At-tirmidhi ati Ibn Majah).
 Bakan naa nitori ima maa toju bo oro oloro ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se so bayi ninu oro re pe:
" إن من حسن إسلام المرء تركه ما لا يعنيه ". رَوَاهُ اَلتِّرْمِذِيُّ
'' dajudaju ninu didara esin Islam omoniyan ni ki o gbe oun ti ko ba kan ju sile " (At-tirmidhi).
 Bakan naa nitori mimu anfaani ni wa fun awon eniyan ati mimu idunnu ba won ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se so ninu oro re pe:
" أحب الناس إلى الله أنفعهم للناس وأحب الأعمال إلى الله سرور تدخله على مسلم أو تكشف عنه كربة أو تقضي عنه دينا أو تطرد عنه جوعا ولئن أمشي مع أخ لي في حاجة أحب إلي من أن أعتكف في هذا المسجد شهرا ومن كف غضبه ستر الله عورته ومن كظم غيظه ولو شاء أن يمضيه أمضاه ملأ الله قلبه رجاء يوم القيامة ومن مشى مع أخيه في حاجة حتى يثبتها له ثبت الله قدمه يوم تزول الأقدام" صحيح الجامع
'' Eni ti Olohun feran julo (ninu awon eniyan) ni eni ti nse awon eniyan ni anfaani julo, ise ti Olohun si feran julo (ninu awon ise) ni idunnu ti o mu ba musulumi tabi inira kan ti o mu kuro fun tabi gbese eyi ti o ba san tabi ebi ti o mu kuro fun, ki nmaa be pelu omo iya mi kan nibi gbigbo bukata re o wumi ju ki nse atipo (itikafu) fun odidi osun kan ninu mosalasi yi lo (mosalasi anabi), enikeni ti o ba kapa ibinu re, Olohun yoo pa ihoho (koko) re mo, atipe enikeni ti o ba pa ibinu re mora leyi ti o jepe ti o ba si fe binu naa o ni agbara bee, Olohun yoo kun okan re pelu irankan daada ni ojo igbende, enikeni ti o ba si duro ti omo iya re nibi gbigbo bukata re titi ti o fi ri gbo, Olohun yoo fi ese re rinle ni ojo ti awon ese yoo maa tase '' (At-tirmidhi).
 Awon oro wonyi kii se oro eniyan lasan bikosepe o je awon oro ilana ofin esin Islam ti o wa lati inu Al-Kurani ati sunnah Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Ti o ba wa jepe eleyi ni ilana esin kan, nje kii se pe o dara ti o si leto ki eniyan tele e, ki o si se iranlowo fun un, tabi o tile wa kere ju ki eniyan si ma gbogun ti rara, ki o si se gbogbo akitiyan re lati je ki o dagba soke ki o si fanka laarin awujo?
 Olorire eniyan ni iru eni ti o ba jere pelu iru esin bayi ni eyi ti yoo fun ni anfaani lati leto si awon irorun ati irora wonyin. Ninu eyi ti o je okunfa ki awon eniyan kan ti won kii se elesin Islam sa seyin fun esin Islam ni awon oun ti won nri latara ibasepo won pelu awon eniyan kan ti won npe apemora Islam musulumi, leyi ti o si jepe esin Islam bowo bose kuro ninu awon ihuwasi wonyi ti ko dara yi, koda won jinna si imo pe apemora re.
 Nitorinaa mo nrankan ki isesi awon musulumi kan ti ko dara ma je gaga ti yoo se okunfa ki o ma mo ododo esin alaponle yi. Awon ona po repete lati ni alekun imo ododo nipa esin Islam, sugbon o gbodo je lati ibi awon orisun ati ipile ti o fokanbale ti o si ni ipile. Mo nbe Olohun ki oje ki iwe yi se anfaani, ki o si je ki o wulo fun oun ti a tori re koo.

 

 
www.islamland.com