IBERE ATI OPIN

IBERE ATI OPIN

IBERE ATI OPIN

البداية والنهاية باللغة اليوروبا

 

 

 

Dr. Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha

د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 

 

Itumo ni ede Yoruba

European Islamic Research Center (EIRC)

المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية

& Abd Ar-Razzaq Isa

Atunto

Ridwan Allah Murtadho

 

 

NI ORUKO OLOHUN, OBA AJOKE, AYE ASAKE ORUN

ORO ISAAJU

 

Ope ni fun Olohun ti O so bayi pe:

 يَا أَيُّهَا الْإِنسَانُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ الْكَرِيمِ (6) الَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّاكَ فَعَدَلَكَ (7) سورة الإنفطار آية ٦-٧

''Ire eniyan ki ni o tan o je nipa Oluwa re Alabukun \\ Eni ti O da o ti O si se (eda) re ni pipe perepere leyin naa O se awon orike re dogbandogba (O si tun gbe o duro daradara).'' Q 82:6-7

Ike ati ige ki o ma ba Anabi Muhammad eni ti o so bayi pe:

أنتم بنو آدمَ، وآدمُ مِن ترابٍ”. صحيح أبي داود

''Omo Adamo ni eyin se, Adamo si wa latara yerupe.'' (Abu dawud).

Ki o ma ba awon ara ile re ati awon omoleyin (Sahabe) re, awon eniyan rere, leyin naa

Dajudaju oro nipa dida aye, bawo lo se bere ati kikojo re je okan ninu awon oun ti o ko airoju ba omoniyan pupo lati igba pipe wa, ni pataki ju lo awon ti kii se musulumi, awon musulumi la ninu wahala nitori pe esin Islam ti so asoye ati asoyan lori oro ri lati igba ti o ti bere, bakan naa ni o si salaye oun ti omoniyan ni bukata si ni alaye ti ko ruju, ti o si tun salaye awon oun ti yoo wulo fun omoniyan. Latara idi eleyi ni awon musulumi se la kuro ninu itese bose eyi ti awon miiran kosi, nibi mimaa mu awon okan o jokan orisirisi aroso ati iwoye wa.

Leyi ti o sepe ni kete ti iwoye kan tabi aroso kan ba ti njade bayi ni omiiran ti yoo je atako fun un yoo si maa tele e. Eleyi ni o fi ndawa loju gbangba pe oun ti Al-Kuran alaponle ati sunnah (ilana) eni esa (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) se alaye re fun wa nipa alamori ti a nsoro re yi je oun ti o fese rinle ti o s ni alaafia. Alaye yi je ododo oro ti o fese rinle, ti ko si si eyikeyi ninu awon oniranran aroso awon ti kii se musulumi lori oro yi ti o le tako o tabi ki o mu oun ti o se deede re wa titi yoo fi di ojo igbende. Nitori pe gbogbo oun ti o ba yato si awon mejeeji ni yoo pada fori sopon ti yoo si yepere niwaju ifirinle lati odo Olohun.

Dajudaju Olohun Oba ti mimo se tire ti ola Re ga, Eleda ile aye eyi ti a foju ri yi ati eyi ti a ko foju ri, O roro kuro lodo awon eda Re ati pe awon eda ni won tun bukata si ti won si je alaini lodo Re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَا أَيُّهَا النَّاسُ أَنْتُمُ الْفُقَرَاءُ إِلَى اللَّهِ وَاللَّهُ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ (15) إِنْ يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ (16) وَمَا ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ بِعَزِيزٍ (17)

"Eyin eniyan alaini ni e je si Olohun, Olohun si ni Oloro Oba Olope \\ Ti O ba fe, yo maa ko yin kuro nile O si maa mu eda tuntun wa \\ Iyen ko si kagara kan ba Olohun. eleyi ko nira fun Olohun.'' Q 35:15-17

Nitori naa igbagbo re ati gbogbo ise rere ti o ba se ni ibamu si oun ti awon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) mu wa lati odo Olohun ni yoo maa ma je anfaani fun o. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنْ تَكْفُرُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ عَنْكُمْ وَلَا يَرْضَى لِعِبَادِهِ الْكُفْرَ وَإِنْ تَشْكُرُوا يَرْضَهُ لَكُمْ

''Bi eyin ba se aimoore dajudaju Olohun naa roro lai si eyin. Ati pe (ko sin i bukata si yin) ko si yonu si aimoore fun awon erusin re. Ati pe bi eyin ba se ope yoo yonu si i fun yin.'' Q 39:7

Ati pe Olohun so ninu egbewa oro lati odo Re (hadith qudusi) pe:

يا عبادي إني حرمت الظلم على نفسي وجعلته بينكم محرما فلا تظالموا, يا عبادي كلكم ضال إلا من هديته فاستهدونى أهدكم، يا عبادي كلكم جائع إلا من أطعمته فاستطعمونى أطعمكم، يا عبادي كلكم عار إلا من كسوته فاستكسونى أكسكم، يا عبادي إنكم تخطئون بالليل والنهار وأنا أغفر الذنوب جميعا فاستغفرونى أغفر لكم، يا عبادي إنكم لن تبلغوا ضري فتضروني ولن تبلغوا نفعي فتنفعوني، يا عبادي لو أن أولكم وآخركم وإنسكم وجنكم كانوا على أتقى قلب رجل واحد منكم ما زاد ذلك في ملكي شيئا، يا عبادي لو أن أولكم وآخركم وإنسكم وجنكم كانوا على أفجر قلب رجل واحد ما نقص ذلك من ملكي شيئا، يا عبادي لو أن أولكم وآخركم وإنسكم وجنكم قاموا في صعيد واحد فسألوني فأعطيت كل إنسان مسألته ما نقص ذلك مما عندي إلا كما ينقص المخيط إذا أدخل البحر، يا عبادي إنما هي أعمالكم أحصيها لكم ثم أوفيكم إياها فمن وجد خيرا فليحمد الله ومن وجد غير ذلك فلا يلومن إلا نفسه” صحيح - رواهُ مسلمٌ

''Eyin erusin Mi; Emi ti se abosi sise ni eewo fun ra mi mo si tun se e ni eewo laarin yin, nitori naa, e ko gbodo se abosi laarin ara yin. Eyin erusin Mi; gbogbo yin patapata ni eni anu (eni ti ko mona otito) ayafi eni ti mo ba fi mona, e toro imona ni odo Mi, maa si fiyin mona. Eyin erusin Mi; gbogbo yin patapata ni eni ti ebi npa ayafi eni ti mo ba fun ni ounje e wa ije imu wa si odo Mi, maa si fun yin ni ounje. Eyin erusin Mi; gbogbo yin patapata ni onihooho ayafi eni ti mo ba wo laso, e maa wa bibo ihooho si odo Mi. emi yoo wo yin laso. Eyin erusin Mi; eyin n dese loru ati losan, Emi si ni mo maa n se aforijin gbogbo ese patapata, nitori naa e maa wa aforijin sodo Mi, Emi yoo se aforijinin fun yin. Eyin erusin Mi; eyin ko le de aaye ti o le mu ipalara bami rara, debi ti e file pa mi lara, be si ni e ko le da aye ti le se anfaani kan fun mi debi ti e o fi le se mi lanfaani Kannkan. Eyin erusin Mi; dajudaju ti awon eni akoko ninu (ti won n be) yin ati awon eni ikeyin ninu yin, pelu awon eniyan ninu yin ati awon alijonnu ninu yin ba je Oluberu Olohun ju lo ninu yin, eleyii ko le se alekun sanmokan ninu ola Mi.  Eyin erusin Mi; dajudaju ti awon eni akoko ninu yin ati awon eni ikeyin ninu yin, pelu awon eniyan ninu yin ati awon alijonnu ninu yin ba da gegebi eni ti o ya pokii ju lo ninu yin, eleyi ko ledin nnkankan ku ninu ola Mi. Eyin erusin Mi; dajudaju ti awon eni akoko ninu yin ati awon eni ikeyin ninu yin, pelu awon eniyan ninu yin ati awon alijonnu ninu yin ba duro si ori ile ti o te perese, ti e wa n toro (orisirisi) nnkan lodo Mi, ti mo si fun onikaluku ni ohun ti n beere, eleyi ko din nnkankan ku ninu ola Mi ayafi bi apejuwe oun ti abere le dinku ninu omi okun nigba ti won ba tii bo inu re (ti o tumo si pe ko din nnkankan ku ninu ola Re). Eyin erusin Mi; dajudaju eleyi ni awon ise yin, ti Mo si n ba yin se akojopo (isiro) won sile fun yin, leyin naa (ni ojo idajo) Maa si san yin ni esan lori re, nitori naa eni ti o ba ba rere pade (ti o gbesan rere) ko yaa dupe fun Olohun, eni ti o ba si ba idakeji pade (ti o gbesan aburu) ki o ma bu enikannkan bi ko se emi ara re.'' (Muslim).

Esin Islam je esin Olohun eyi ti O yonusi fun awon erusin Re ti O si se ni ilana fun won. Omoniyan ni apapo ni ogidi bukata si esin yin pupo, ki alamori aye won ati isemi won le wa letoleto, yala ni eyo kookan won ni tabi ni apapo, eyi ti o niise pelu oro abele ni tabi tode. O je esin ti o ni akolekan pelu awon oun ipile ti ko si fi owo dengbere mu awon aketun oro isemi omoniyan. O se deedee laarin oun emi ati tara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا

''Lo nii ni yi Mo se esin yin ni pipe fun yin ati pe Mo se asepe idera Mi leyin lori ati pe Mo yonu si Islam ni esin fun yin.'' Q 5:3.

Oriire ti o ga ni o n be fun omoniyan nibi lilo re ni ile aye nitori pe won yoo ni isinmi ati ifokanbale okan pelu itunu emi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ (21:107)

''Awa ko si fi ise imisi ran o bi ko se pe ki o le je ike fun gbogbo eda.'' Q 21:107.

Ti o ba si di ni orun won yoo jere pelu iyonu Oluwa gbogbo agbaye ati sise gbere ninu ogba idera (Al jannah). Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ كَانَتْ لَهُمْ جَنَّاتُ الْفِرْدَوْسِ نُزُلًا (107) خَالِدِينَ فِيهَا لَا يَبْغُونَ عَنْهَا حِوَلًا (108)

''Dajudaju awon ti won gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, awon ogba idera naa (Al firidaosi) ti wa fun won ni ibudesi Olusegbere ni won ninu re, won ko si ni fe wa iyipada kuro nibe.'' Q 18:107-108.

O je esin ti aabo n be lori re lati odo Olohun wa titi di ojo agbende. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ (9)

''Dajudaju Awa ni A so (Al – Qur’aan) iranti naa kale ati pe dajudaju Awa ni Oluso fun un.'' Q15:9.

Bi o tiwu ki awon ota esin gbiyanju to lati fi abuku ati aaye kan an, dajudaju Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

“لَا يَأْتِيهِ الْبَاطِلُ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَلَا مِنْ خَلْفِهِ تَنْزِيلٌ مِنْ حَكِيمٍ حَمِيدٍ (42)”

''Ibaje ko nii kan - an lati iwaju re, beeni ko le gba eyin wa ba a, imisi kan ni to sokale lati odo (Oba) Ojogbon (Oba) ti eyin to si.'' Q 41:42.

Nikeyin, oro Olohun ati ase Re naa ni yoo leke gbogbo oro, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّ الَّذِينَ يُحَادُّونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ كُبِتُوا كَمَا كُبِتَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ وَقَدْ أَنْزَلْنَا آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ مُهِينٌ (5)

''Dajudaju awon eni ti won tako oro Olohun ati ojise Re A o yepere won gegebi ati yepere awon eni ti won siwaju won; dajudaju A so awon amin ti o han kale. Iya ti I yepere n be eda fun awon alaigbagbo.'' Q 58:5.

Pelu gbogbo igbiyanju awon ota esin Islam lati kodi awon eniyan lati wonu esin naa ati bi won se ngbogun ota si, won yoo pada jeka abamo nikeyin gbeyin latara ailaseyori ati ofo ti yoo ba won. Olohun ti ola re ga so bayi pe:

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ لِيَصُدُّوا عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ فَسَيُنْفِقُونَهَا ثُمَّ تَكُونُ عَلَيْهِمْ حَسْرَةً ثُمَّ يُغْلَبُونَ وَالَّذِينَ كَفَرُوا إِلَى جَهَنَّمَ يُحْشَرُونَ (36)

''Dajudaju awon eni ti won se aigbagbo, won nna owo won nitori ati seri awon eniyan kuro ni oju ona Olohun. Won si n naa lo (bee), leyin naa o n maa di abamo fun won. Leyin naa A o si maa bori won Ati pe awon alaigbagbo A o ko won jo sinu ina jahanama ni.'' Q 8:36.

Ofin Olohun yoo waye, ase Re yoo se esin Re yoo si maa seku lo lailai. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يُرِيدُونَ لِيُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَاللَّهُ مُتِمُّ نُورِهِ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ (8)

''won ngbero lati fi (oro) enu won pa imole Olohun, Olohun yoo si mu imole Re tan kari, koda bi awon alaigbagbo ko fe.'' Q 61:8.

Olohun se adehun pe Oun yoo ran esin naa lowo Oun yoo si gbe bori gbogbo esin, Olohun so bayi pe:

هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَى وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَكَفَى بِاللَّهِ شَهِيدًا (28)"

''Oun (Olohun) ni Eni ti O ran ojise Re pelu itosona ati esin ododo (esin Islam) ki O le fi bori gbogbo esin kesin (miiran). Olohun si to ni Eleri.'' Q 48:28.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) naa so ninu oro re bayi pe:

ليبلغن هذا الأمر ما بلغ الليل والنهار ولا يترك الله بيت مدر ولا وبر الا أدخله الله هذا الدين بعز عزيز أو بذل ذليل عزا يعز الله به الإسلام وذلا يذل الله به الكفر” صحيح رواه أحمد والطبراني

'' Dajudaju alamori (esin) yi yoo de gbogbo ibi ti ile ti nsu ti ile si ti nmo, Olohun ko ni yo ile kan sile yala ni aarin ilu tabi igberiko bikosepe Olohun yoo mu esin yi wo ibe pelu yala iyi abiyi ni o tabi pelu iyepere oluyepere, iyi kan eyi ti o jepe Olohun yoo fi pon esin Islam le ati iyepere ti Olohun yoo mu ba awon alaigbagbo'' (Ahmad ati At tabaraani).

Ni paapaa esin Islam se deedee lori adamo omoniyan, o si tun n se imuse afojusun won pelu sise onigbowo ifokanbale won ni abala gbogbo eto patata, gegebi eyi ti o niise pelu emi omoniyan, eto awujo, eto isuna, eto isejoba ati beebee lo. Pelu gbogbo oun ti Olohun se fun esin yi ninu oun agbara abele eyi ti o jepe okunfa re naa ikunlowo Olohun ti mimo n be fun ti ola Re si ga. Eleyi ni o fa ti esin naa fi ngbooro ti awon eniyan si nwonu re nijo nijo biotile jepe iranlowo inawo ati inara ti o nri kere jojo ti opolopo awon musulumi si je alai lakakun re ni abala ipokiki re ati pipe awon eniyan sinu re.

Ni idakeji, awon ota esin nsapa won si ngbogun pelu gbogbo oun ti n be ni ikapani won ni agbara yala ti owo ni tabi agbara omoniyan koda won tun nlo omo ogun lati gbogun tii ati lati seri awon eniyan kuro nibe ati sise awon oun ti yoo je idiwo fun ipepe re, bakan naa ni won tun ma nko ipaya ba awon pelu imaa pe ni esin ero eyin, igbesumomi ati esin ti ko ni olaju. Ko si oun ti o fa eleyi ju wi pe won ri awon eto esin Islam si oun ti yoo je idiwo fun won lori awon afojusun won lati jegaba lori awon eniyan won tabi lori agbaye omoniyan lapapo.

Leyi ti o si jepe esin Islam se ikoja ala, abosi sise ati ijegaba oniranran ni eewo, o si tun se siso omoniyan di eru fun elomiiran leyin Olohun ni eewo, iru ise yi yoo tun wa buru jai nigbati o ba niise pelu awon alailagbara ninu awon eniyan. Esin Islam je esin kan ti o tako ijegaba awujo kan lori omiiran, tabi ijo kan lori ijo miiran, tabi awon eniyan kan lori awon eniyan miiran, Olohun ti ola re ga so bayi pe:

يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِنْدَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ

''Eyin eniyan, dajudaju A da yin latara okunrin kan ati obinrin kan A si se yin ni Orile ede ati iran iran ki e le ba maa mo ara yin. Dajudaju eni ti o ni aponle ju lo ninu yin lodo Olohun ni eni ti n beru (Re) ju lo.'' Q 49:13.

Eyi ti yoo je ibuseri si mi ninu iwe kekere yi naa ni Al kurani Alaponle, eyi ti o tako ki imo nipa ibere ideda je eyi ti yoo wa lati ara oun ti omoniyan ba mo fun ra re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

مَا أَشْهَدْتُهُمْ خَلْقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَا خَلْقَ أَنْفُسِهِمْ وَمَا كُنْتُ مُتَّخِذَ الْمُضِلِّينَ عَضُدًا (51)"

''Emi ko pe won sibi yala dida won sanmo ati ile, tabi dida awon gan alara. Emi ko si mu awon asini lona ni oluranlowo.'' Q 18:51.

Bakan naa ni oro ti o feserinle eyi ti o wa lati odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma baa). Nko ni so asopo laarin oun ti o wa lati inu Al kurani ati awon oro ti o feserinle lati odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma baa) pelu imo ode oni ati awon iwoye re pelu awon abajade imo ijinle re, nitori pe eyikeyi oun ti o ba se feserinle ninu awon iwoye ni asiko yi ni o le di lola ki awon iwadi imo ijinle miiran tako o ki o si di oun ti ko ni ba igba mu mo. Eleyi si ni oun ti n sele ni asiko ti a wa yi, leyi ti o jepe opolopo ninu awon iwadi imo ijinle ti o ti koja ti o si feserinle ni igba naa ni imo ode oni so pe ko ri bee mo!! Ododo ni oro Olohun Oba ti o gbongbon ti o so bayi pe:

وَمَا أُوتِيتُمْ مِنَ الْعِلْمِ إِلَّا قَلِيلًا (85)

'' Awa ko si fun yin ninu imo bi ko se die.'' Q 17:85

Dr. Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha

www.islamland.com

IGBAGBO ODODO NINU OLOHUN

Dajudaju ini igbagbo ododo ninu Olohun ati gbigba pe O n be laaye pelu sise afirinle ije okansoso Re je ipile ofin esin Islam. Nitori pe ti awon wonyi ba ti feserinle lodo omoniyan gbogbo awon origun igbagbo yoku ni yoo tele e. Eleyi si ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so nipa re nigba ti malaika Jubireel bi leere bayi pe; so fun mi nipa igbagbo, ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wi pe:

أن تؤمن بالله وملائكته وكتبه ورسله واليوم الآخر وتؤمن بالقدر خيره وشره...”صحيح مسلم

”ki o ni igbagbo ninu Olohun ati awon Malaika Re ati awon Tira Re ati awon Ojise Re ati ki o si ni igbagbo ninu ebubu (kadara) eyi ti o dara ninu re ati eyi ti o buru ninu re…” (Muslim)

 

TANI OLOHUN

Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

هُوَ الْأَوَّلُ وَالْآخِرُ وَالظَّاهِرُ وَالْبَاطِنُ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ (3)

''Oun ni Eni akoko Oun si ni Eni ikeyin Oun ni O han (pelu ami bibe Re) Oun naa si ni O sunmo Oun ni O mo gbogbo nnkan.'' Q 57:3

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

هُوَ اللَّهُ الَّذِي لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْمَلِكُ الْقُدُّوسُ السَّلَامُ الْمُؤْمِنُ الْمُهَيْمِنُ الْعَزِيزُ الْجَبَّارُ الْمُتَكَبِّرُ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يُشْرِكُونَ (23) هُوَ اللَّهُ الْخَالِقُ الْبَارِئُ الْمُصَوِّرُ لَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَى يُسَبِّحُ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (24)

''Oun ni Olohun, Eni ti ko si olohun miiran ayafi Oun, Oba (gbogbo eda) Eni mimo ju lo, Eni ti o la nibi gbogbo abuku Eni ti gbogbo eda fokanbale si pe ko le se abosi, olujeri lori gbogbo ise eda, Eni ti o le je eda nipa, Alagbara, Eni ti O tobi ju lo (ti O ni motomoto), Mimo fun Olohun, O mo ju ohun ti won fi n se orogun pelu Re lo \\ Oun ni Olohun Oluda eda, Olupele eda da, Oluyaworan eda; ti Re ni awon oruko ti o dara ju lo. Gbogbo eni ti n be ninu sanmo ati ile n se afomo fun un, Oun sii ni Alagbara Ologbon.'' Q 59:23-24.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

اللَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ (255)

''Olohun, ko si olohun miiran ti ijosin to si ayafi Oun, Alaaye, Oludawa, Oogbe ki i ta A, beeni kii sun. Ti Re ni oun gbogbo ti o wa ni sanmo ati ohun gbogbo ti o wa ni inu ile. Ta ni eni ti o le sipe ni odo Re, ayafi pelu ase Re. O mo oun ti n be ni iwaju won ati oun ti n be ni eyin won, won ko si le ro kirika kinikan ninu imo Re ayafi oun ti O ba fe. Aga (ola Re) gbaaye ju awon sanmo ati ile lo. Iso awon mejeeji ko da A lagara. Oun ni Eni ti O ga (ni ola) ti O si tobi (ni ogo).'' Q 2:255.

Ninu ofin ati ilana esin Islam Olohun je Oun ti a mo ti ko si rujuruju kannkan nibe rara, ofin ati ilana esin Islam se alaye ti o kun rere nipa pe tani Olohun ki si ni awon iroyin Re ati pe awon ona wo ni a fi le de odo Re.

Nitori naa Olohun Oba mimo ti ola Re ga:

1 - Oludeda ti O seda gbogbo nnkan patapata, eyi ti ile aye yi ntoka si pelu gbogbo oun ti o ko sinu ninu awon eda orisirisi, Olohun ti ola Re ga nso bayi pe:

قُلِ انْظُرُوا مَاذَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا تُغْنِي الْآيَاتُ وَالنُّذُرُ عَنْ قَوْمٍ لَا يُؤْمِنُونَ (101)

''so (fun won) pe; E woye si sanmo ti n be ni sanmo ati ile. Awon arisami ati ikilo ko si sanfaani fun ijo ti ko gbagbo ni ododo.'' Q 10:101.

2 - Okansoso, Aso, Eni ti ko ni orogun, Oba ti a ma nronu kan, ko ni orogun nibi ola Re, enikan ko bi I Oun naa ko si bimo, ko si alafijo fun UN, ko si ni enikeji, beeni ko ni iyawo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ (1) اللَّهُ الصَّمَدُ (2) لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ (3) وَلَمْ يَكُنْ لَهُ كُفُوًا أَحَدٌ (4)"

''So pe; Oun ni Olohun Oba Okansoso \\ Eda ni bukata si, ti oun ko sin i bukata kan kan si won, \\ ko bimo bee si ni a ko bii \\ Bee si ni ko si enikan ti o jo O.'' Q 112: 1-4.

3-  Onimimo ti imo Re rokirika gbogbo nnkan patapata, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا يَعْزُبُ عَنْ رَبِّكَ مِنْ مِثْقَالِ ذَرَّةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ وَلَا أَصْغَرَ مِنْ ذَلِكَ وَلَا أَكْبَرَ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُبِينٍ (61)"

''Bee sini kini kan ko pamo fun Oluwa re, gegebi odiwon omo inu igun ninu ile ati ni sanmo ibaa kere tabi ki o tobi ju iyen lo ayafi ki o maa be ninu ninu akosile to yanju (Tira).'' Q 10:61

4-  Asemi gbere Eni ti ko ni ku. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

هُوَ الْحَيُّ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ فَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ (65)"

''Oun ni Alaaye ko si olohun miiran ti ijosin to si ayafi Oun; Nitori naa e maa ke pee (ki e je) n se olusafomo esin fun Un. Ope ni fun Olohun Oluwa gbogbo eda.'' Q 40:65.

5 - Oni deedee, kii se ijanba, kii si se abosi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَنَضَعُ الْمَوَازِينَ الْقِسْطَ لِيَوْمِ الْقِيَامَةِ فَلَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا وَإِنْ كَانَ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِنْ خَرْدَلٍ أَتَيْنَا بِهَا وَكَفَى بِنَا حَاسِبِينَ (47)"

''Awa yoo fi osunwon ti o se deedee lele ni ojo igbende, Nitori naa, Awa ko nii se abosi kan kan fun emi kan. Ti o ba se pe osunwon (ise eniyan) je iwon eso [ kardal] bin – intin. A maa mu – un wa, Awa si to ni Olusiro.'' Q 21:47.

6-  Ko si oun ti o dabi Re yala nibi paaapaa Re ni tabi nibi awon iroyin Re tabi nibi awon ise Re, Oun ni gbogbo pipe ti o lafijo n be fun, O pe nibi paapaa Re, nibi awon iroyin Re ati nibi awon ise Re, oun ti O ba fe nikan ni yoo maa sele, oun ti ko ba fe ko le sele. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

اللَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ لَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَى (8)

'' Olohun, ko si Olohun ti ijosin to si afi Oun. Oun ni O ni awon oruko ti o dara ju lo.'' Q 20:8.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

فَاطِرُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ جَعَلَ لَكُمْ مِنْ أَنْفُسِكُمْ أَزْوَاجًا وَمِنَ الْأَنْعَامِ أَزْوَاجًا يَذْرَؤُكُمْ فِيهِ لَيْسَ كَمِثْلِهِ شَيْءٌ وَهُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ (11)

''(Oun ni) Olupileda awon sanmo ati ile. O si se yin ni tako¬ tabo lati inu ara yin, o tun se eda awon eran – osin lako labo, Oun mu yin po sii (nipa isada yin ni akoo ati abo). Ko si kini kan ti o dabii Re; (Olohun) Oun ni Olugboro Ariran.'' Q 42:11.

Ati pe Olohun ti ola Re ga, ti Re ni awon oruko ati iroyin ti o ntoka lori pipe ati gbigbongbon Re, biotile jepe oro nipa eleyi ti wa ninu iwe miiran ti mo ko, ti mo si se alaye ti o kun sinu re, eni ti o ba fe alekun alaye nipa abala yi ki o wo inu iwe naa. Sugbon a gbodo mo wi pe awon oruko ati iroyin Re wonyi ko ni onka kan gbogi, nitori oro ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:

"ما قال عبد قط إذا أصابه هم أو حزن اللهم إني عبدك بن عبدك بن أمتك ناصيتي بيدك ماض في حكمك عدل في قضاؤك أسألك بكل اسم هو لك سميت به نفسك أو أنزلته في كتابك أو علمته أحدا من خلقك أو استأثرت به في علم الغيب عندك أن تجعل القرآن ربيع قلبي ونور بصري وجلاء حزني وذهاب همي إلا أذهب الله همه وأبدله مكان حزنه فرحا" أخرجه أحمد وابن حبان

'' Erusin (Olohun) kan ko ni so nigba ti ipaya tabi ibanuje ba de ba a pe 'Ire Oluwa (mi) dajudaju erusin Re ni mo je, omo erusin Re lokunrin, omo erusin Re lobinrin, owo Re ni aao ori mi wa (idari gbogbo oro) wa, idajo Re ti gba iwaju lori mi, yoo se lori mi, deedee si ni ipe ebubu Re lori mi, mo n be O pelu gbogbo awon oruko eyi ti n be fun O, eyi ti O so ara Re ni, tabi eyi ti O sokale sinu Tira Re (awon Tira ti a fi ran awon Ojise), tabi eyi ti O fi mo okan ninu awon eda Re, tabi eyi ti O dayo fi pamo sinu imo koko lodo Re, pe ki O se Al Kurani ni (okunfa) ibale emi fun mi ati ki O se ni imole okan mi, ati olutilo fun ibanuje mi, ati olugbe ipaya mi kuro, ayafi ki Olohun O mu ipaya kuro fun un ki O si fi idunnu ropo ibanuje re.'' (Ahmad ati Ibnu Hibban).

Olohun ti ola Re ga, ni awon oruko ati awon iroyin sugbon ti won yato gedengbe si ti awon eda Re. Olohun, Oun ni Adeda Eni ti o seda gbogbo nnkan patapata, bibe Olohun ko dabi bibe eyikeyi nnkan, Olugboro ni; igboro Re ko dabi ti eyikeyi nnkan, Oluriran ni; iriran Re ko dabi iriran eyikeyi nnkan, bayi ni o se ri ninu gbogbo awon oruko ati awon iroyin Re, Oun ni O so nipa ara re pe: 

وَلَا يُحِيطُونَ بِهِ عِلْمًا (110)

''(Awon eda) awon ko si le ni imo ohun gbogbo nipa Re (Olohun).'' Q 20: 110.

Nitori pe O (Oba ti O ma ganga ti ola Re ga) koja oun ti lakaye omoniyan le lepa ba, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

لَا تُدْرِكُهُ الْأَبْصَارُ وَهُوَ يُدْرِكُ الْأَبْصَارَ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ (103)

'' Awon oju eda ko le ka Olohun (nitori titobi Re) Oun si rogba yi awon oju ka Oun ni Alaaanu, Olumo – ikoko.'' Q 6:103.

Latara pe adamo emi omoniyan ni ki o maa beere, ati ki o maa se iwadi nipa orisirisi nnkan ati ki o maa gbiyanju lati mo kulekule nipa nnkan kookan, won se imaa se ironu nipa idera Olohun ati awon amin Re ti ntoka lori gbigbongbon ati imaa be Re, ni ijosin fun Olohun Abiyi. Sugbon ko leto lati maa se ironu nipa paapaa Olohun, nitori pe eleyi koja lakaye omoniyan, o si tako igbagbo (ninu Olohun). Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) so pe: awon eniyan kan ninu awon omoleyin Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) wa bi leere wi pe: 

إنا نجد في أنفسنا ما يتعاظم أحدنا أن يتكلم به. قال:"وقد وجدتموه؟” قالوا: نعم. قال: ”ذاك صريح الإيمان”رواه (مسلم، وأبو داود، والنسائى)

''A n se akiyesi ninu emi wa (awon orisirisi royi royi lati odo esu) awon ohun ti ko se e maa so jade lenu fun enikookan wa, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o maa ba) wa beere pe; sugbon o ti sele si yin? Won si dahun wi pe beeni, o si dawon lohun wi pe: Titako yin ti e ni si irori buburuu si ni a n pe ni ogidi igbagbo.'' (Muslim ati Abu Dawud ati An Nasai)

 * Ninu awon oun ti nda won lokan ru yi ni bii: tani o da Olohun?, bawo lo se ri? Ibo ni O ti wa? Ati beebee lo, idi niyi ti o fi wuwo lati so iru re jade latara wi pe ko si oun ti o leto lati maa beere ninu awon nnkan wonyi ati awon oun ti o jo o.

 * Oro Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o so pe '' eleyi n ogidi igbagbo '' tumo si pe; ki eniyan fi emi ko iru awon nnkan bayi ntoka si ododo igbagbo ninu Olohun nitori pe ko leto lati maa ronu nipa paapaa Olohun, ati pe eleyi je ise esu lati so omoniyan nu pelu awon royi¬ royi orisirisi.

Esu ni o ma nje okunfa iru awon ironu buruku bayi, o si maa n lo eyi gege bi ategun lati so omoniyan nu kuro ni oju ona esin Olohun. O si ti se ileri lori eleyi lati igba iwase, Olohun ti ola Re ga so nipa eleyi pe: 

قَالَ أَرَأَيْتَكَ هَذَا الَّذِي كَرَّمْتَ عَلَيَّ لَئِنْ أَخَّرْتَنِ إِلَى يَوْمِ الْقِيَامَةِ لَأَحْتَنِكَنَّ ذُرِّيَّتَهُ إِلَّا قَلِيلًا (62)

'' O si wi pe: O ha le ri iro fun mi, nipa eyi ti O ponle jumi lo yii, dajudaju ti Iwo ba lomi lara di ojo ajinde, dajudaju emi yoo pa awon aromodomo re run ayafi die (ninu won).'' Q 17:62.

Eleyi ko je nnkankan ju royiroyi lati odo esu lo, eyi ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti se alaye ti o yanju lori re pelu oro ti Omo Abbas so pe; arakunrin kan wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) o si so pe; ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) emi mi ma nba mi so oro kan leyi ti o je wi pe mo nife si ki njabo lule lati oke sanmo ju ki nso iru oro bee jade lo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa dahun wi pe:

الله أكبر الله أكبر الله أكبر، الحمد لله الذي رد كيده إلى الوسوسَةِ” صحيح أخرجه أحمد، وأبو داود

''Olohun ni O tobi ju lo Olohun ni O tobi ju lo, ope ni fun Olohun Eyiti O yi ete esu pada si royiroyi nikan.'' (Ahmad ati Abu Dawud).

Nigba ti esu ba fe ko royiroyi ba o lori awon oro ti o koja oye ati lakaye omoniyan, yara lo imoran ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o so lasotele:

لايزال الناس يتساءلون حتى يقال هذا: خلق الله الخلق، فمن خلق الله ؟ فمن وجد من ذلك شيئاً فليقل: آمنت بالله” متفق عليه واللفظ لمسلم

''Awon eniyan ko ni ye leni ti yoo maa beere titi yoo fi so bayi pe: Olohun da awon eda, ta wa ni o da Olohun? Enikeni ti eleyi ba sele si ki o yara so pe; mo nigbagbo ninu Olohun.” (Al Bukhari ati Muslim).

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun se alaye ona abayo ninu iru ironu bayi pe; esu yoo maa wa ba enikookan ninu yin ti yoo si maa so fun pe; tani o da kini? Tani o da kini? Titi yoo fi so pe; tani o da Oluwa re? ti oro ba ti de bi bayi ki o yara fi Olohunwa isora (kuro ni odo esu) ki o si jawo ironu bayi.'' (Al Bukhari ati Muslim).

Ododo ni oro Olohun ti O so pe:

وَإِمَّا يَنْزَغَنَّكَ مِنَ الشَّيْطَانِ نَزْغٌ فَاسْتَعِذْ بِاللَّهِ إِنَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

''Bi iseri lati odo Esu ba waa ba o, fi oruko Olohun wa iso. Dajudaju Oun ni Olugboro Olumo.'' Q 7:200

 

 

 

AWON ITOKA LORI BIBE OLOHUN (TI OLA RE GA)

Dajudaju gbogbo oun ti n be ninu aye yi ni eda Olohun ni o ntoka lori bibe Olohun ni ti paapaa ati lai niye meji ninu wi pe Eni ti O da awon eda Oun naa ni Olohun ti mimo n be fun ti ola Re si ga. Gbogbo awon onilakaye pipe ninu eniyan ti adamo won si ni alaafia ni won mo eleyi. Sugbon awon ti won ntako bibe Olohun nfe lati ri awon eri ati itoka ti awon yoo ri fun ra won pelu awon eya ara ti a fi ma nmo bibe nnkan (oju,eti,owo,imu ati ahon) siwaju ki awon to le gbagbo wi pe Olohun n be.

Leyi tosi jepe alabosi niwon lori imaa beere fun awon nnkan wonyi siwaju ki awon to le ni igbagbo ninu bibe Olohun, nitori pe won ni igbagbo si bibe awon nnkan orisirisi miiran leyin Olohun ninu awon oun ti n be ni aye ti won ko si foju ri won, sugbon latara pe won ri awon oripa ati awon amin won ti o n sele ni orile aye biotile jepe won ko mo paapaa ideda won.

Won ni igbagbo si wi pe ile ni agbara lati fa nnkan mora (lala to roke ile lo nbo), biotile jepe won ko ri agbara yi sugbon won ri oripa re wi pe gbogbo nnkan ti o ba lo soke ni yoo pada wa si ile, bakan naa ni won ni igbagbo si agbara irin (magineti) ti o nfa irin miiran mora latara oripa re ti won ri biotile jepe won ko ri agbara naa ti o nfa irin mo irin, bakan naa ni won tun ni igbagbo si bibe lakaye omoniyan biotile jepe won kori lakaye naa sugbon won ri awon oripa mimaa be re.

Eyi ti o si daju ni wi pe awon eya ara wonyi (oju, eti, owo, imu ati ahon) ma n se asise nigba miiran nibi awon ojuse won, ti a si ma nmo awon asise wonyi leyin oreyin latara lakaye. Fun apere; ti a ba ti opa bo inu omi, yoo han siwa gegebi enipe opa naa ti kan, bakan naa ti a ba nwo awon ila ti o se deedee ara won ti won si wa ni egbe ara won lati ookan, yoo da gegebi enipe won ko si ni egbe ara won, bakan naa ni a ma nni igbonmo ni gbogbo igba pe a nrin ti ori wa si nlo si oke, yala nigba ti a ba wa ni opin ariwa ni tabi a wa ni opin gusu tabi ni ori ile ti o te perese. Gbogbo awon eleyi ati iru re ni o fi nye wa yekeyeke wi pe dajudaju awon eya ara wonyi (oju, eti, owo, imu ati ahon), ti ko ba si lakaye fun omoniyan won ko ba je ki a se asise nibi paapaa awon nnkan pupo, bakan naa ti kii ba se pe omoniyan ni lakaye ni ko ba ma ti si oun ti nje imo amodaju.

Nje oro awon ti won gba pe oun ti a fi le mo amodaju nipa nnkan naa ni awon eya ara marun wonyi wa se deedee bi? Nje won wa se deedee pelu emi ara won bi, nigba ti won ko lati gbagbo ninu bibe Olohun nitori pe won ko mo o latara awon eya ara marun wonyi? Ti o si je pe pelu awon amin ati oripa ti won ri nikan ni won fi gbagbo ninu paapaa awon oun ti won ko fi oju ri wonyi.

Imaa wa tabi beere fun awon oun ti awon eya ara marun yi ba se afirinle re ki a to le ni igbagbo si bibe Olohun je oun ti o gbe opolopo ninu awon eniyan jinna si oju ona ododo ti o to lati mo Olohun pelu ironu si awon amin ati awon eda Re ni orisirisi, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا هَامَانُ ابْنِ لِي صَرْحًا لَعَلِّي أَبْلُغُ الْأَسْبَابَ (36) أَسْبَابَ السَّمَاوَاتِ فَأَطَّلِعَ إِلَى إِلَهِ مُوسَى وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ كَاذِبًا وَكَذَلِكَ زُيِّنَ لِفِرْعَوْنَ سُوءُ عَمَلِهِ وَصُدَّ عَنِ السَّبِيلِ وَمَا كَيْدُ فِرْعَوْنَ إِلَّا فِي تَبَابٍ (37)

''Firiaona wi pe: ire Hamana mo ile ti o ga fiofio kan fun mi nitori ki emi le de awon ona naa. \\ Awon ona (inu) sanmo nitori emi ki emi le yoju wo Olohun Muusaa, nitori pe emi ni ro o si opuro. Gegebayi ni a se buburu ise Firiaona ni o so fun - un, A si se e lori kuro ni oju ona (otito). Ete Firiaona ko je sanmokan bikose ofo.'' Q 40:36-37.

Isesi yi kii se oun ti o mo lori igbakan yato si omiiran, bikosepe o je isesi awon olutako ti Olohun ati awon olupe oro Olohun ni iro latara aimokan lati atijo wa. Ni paapaa Olohun ti ola Re ga ti so nipa isesi pe:

وَقَالَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ لَوْلَا يُكَلِّمُنَا اللَّهُ أَوْ تَأْتِينَا آيَةٌ كَذَلِكَ قَالَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ مِثْلَ قَوْلِهِمْ تَشَابَهَتْ قُلُوبُهُمْ قَدْ بَيَّنَّا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ (118)

''Awon ti ko nimo wi pe: Eese ti Olohun ko ba wa soro tabi ki aayah (amin) kan wa ba wa; (awa iba gbagbo) bayi ni awon ti o ti won siwaju won ti so iru oro wonyi, okan won jo ara won, dajudaju A kuku se alaye awon aayah fun awon eni ti o mo amodaju.'' Q 2:118.

Tabi latara igberaga won, Olohun ti ola Re ga ti so bayi pe:

وَقَالَ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْنَا الْمَلَائِكَةُ أَوْ نَرَى رَبَّنَا لَقَدِ اسْتَكْبَرُوا فِي أَنْفُسِهِمْ وَعَتَوْا عُتُوًّا كَبِيرًا (21) يَوْمَ يَرَوْنَ الْمَلَائِكَةَ لَا بُشْرَى يَوْمَئِذٍ لِلْمُجْرِمِينَ وَيَقُولُونَ حِجْرًا مَحْجُورًا (22)

''Awon eni ti ko ni reti pelu ipade Wa (ni orun), won so pe: kin i o fa a ti won ko fi so kale fun wa, tabi (ki ni o fa a) ti awa ko fi ri Oluwa wa ni ile – aye yii? Dajudaju won se motomoto ninu emi won, won si gbe agbere ti o tobi \\ Ni ojo ti won ba ri Malaika, ko nii si iro idunnu fun won. // Ranti ojo ti won yoo ri Malaika, ko si ni si iro idunnu fun awon elese ni ojo naa (Awon Molaaika) yo si so pe: Eewo Eewo (ni iro idunnu fun eyin elese).'' Q 25:21-22.

Tabi latara abosi, eleyi si ni isesi awon Yehuudi lati atijo, Olohun ti ola Re ga so nipa won pe:

وَإِذْ قُلْتُمْ يَا مُوسَى لَنْ نُؤْمِنَ لَكَ حَتَّى نَرَى اللَّهَ جَهْرَةً فَأَخَذَتْكُمُ الصَّاعِقَةُ وَأَنْتُمْ تَنْظُرُونَ (55)

''E si se iranti Nigba ti eyin so pe: ire Muusaa a ki yoo gba o gbo ayafi ki a ri Olohun ni ojukoroju, Nitori naa, ohun igbe lati inu Sanmo gba yin mu, e sin wo boo.'' Q 2:55.

 

 

 

NINU AWON ERI TI O NTOKA SI BIBE OLOHUN

ALAKOOKO: Latara Adamo Omoniyan, eyi ti o ni alaafia Ti O Ni Alafia: Dajudaju gbogbo omoniyan ti adamo re ni alafia ti laakaye re si duro deedee ni yoo mo amodaju wi pe ko rorun ki a ri eda lai si eni (Adeda) ti o da a ati pe sanmokan ko le sele lai ma ni ohun ti o sokunfa re. Fun apere, ti eniyan ba wo inu yara ti o si ba tabili ninu re yoo mo dajudaju pe tabili naa ko wo inu yara naa fun ra re, sugbon enikan ni yoo gbe wo inu yara naa. Ni paapaa, larubawa oko ti o ngbe ni aginju ti adamo re ni alafia ko salai mo eleyi, ni igba ti won bi i leere wi pe bawo ni o se mo Oluwa re? o dahun lai fota pe, pelu ohun ti Olohun fi ta a lore ninu adamo re ti o ni alafia wi pe: igbe rakunmi maa ntoka lori (irekoja tabi itedo) rakunmi (si aaye kan), oju ese (ni oju ona) si maa ntoka lori ikoja (eniyan), orun dudu kirikiri, ati osan ti n wa ti n lo, ati sanmo ti o kun fun orisirisi irawo, pelu ile ti o kun fun oju ona repete, pelu awon odo nla nla ti o kun fun igbi omi, se eleyi ko wa to lati toka lori (bibe) Oba Alaanu Olu funni niro?

Mo fi Oluwa mi bura laisi iyemeji wi pe; oun ntoka lori bibe Re ati lori titobi Re ati imu yanyan ideda Re.

ELEKEJI: Awon Aayah (Ese Oro) Al-Kurani Alaponle: ogooro ninu awon aayah Al Kurani Alaponle ni o maa n pepe lo sibi iwoye si ile aye ti a wa yi ati ironu si awon oun ti o wa nibe ni orisirisi awon eda Olohun, eleyi ti o ntoka laini iyemeji ninu lori bibe Olohun Adeda ti O ndari gbogbo nnkan, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

قُلِ انْظُرُوا مَاذَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا تُغْنِي الْآيَاتُ وَالنُّذُرُ عَنْ قَوْمٍ لَا يُؤْمِنُونَ (101)

''Wi pe: E wo ohun ti o wa ni sanmo ati ile. Awon arisami ati ikilo ko sanfani fun awon eniyan ti ko ni igbagbo ododo.'' Q 10:101.

1- Ile aye yii ati bi won se se eda re ni ona ti o gunrege ati bi won gbe e kale ni ona ti o yani lenu ti ko ni ekeji, ti o kun fun awon irawo orisirisi ti nlo ti nbo ati awon agbaye oniran ran ti o wa ni sanmo, leyi ti o je pe ti okan ninu won ba yese gere kuro ni oju ona re, ajalu nla nla ti ko see fenu so ni yoo maa sele ni orile aye yi. Ta wa ni eni naa ti o di won mu lati igba iwase titi di oni yi, ti o si je ki won maa rin leseese ati leto leto lori oju ona won? Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

خَلَقَ السَّمَاوَاتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا وَأَلْقَى فِي الْأَرْضِ رَوَاسِيَ أَنْ تَمِيدَ بِكُمْ

''O da awon sanmo laini opo ti e leri, O si fi awon oke nlanla se eekan sinu ile ki o ma baa maa mi mo yin (lese).'' Q 31:10

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

فَسُبْحَانَ اللَّهِ حِينَ تُمْسُونَ وَحِينَ تُصْبِحُونَ (17) وَلَهُ الْحَمْدُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَعَشِيًّا وَحِينَ تُظْهِرُونَ (18) يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ وَيُحْيِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا وَكَذَلِكَ تُخْرَجُونَ (19) وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَكُمْ مِنْ تُرَابٍ ثُمَّ إِذَا أَنْتُمْ بَشَرٌ تَنْتَشِرُونَ (20) وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُمْ مِنْ أَنْفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُمْ مَوَدَّةً وَرَحْمَةً إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (21) وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِلْعَالِمِينَ (22) وَمِنْ آيَاتِهِ مَنَامُكُمْ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَابْتِغَاؤُكُمْ مِنْ فَضْلِهِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَسْمَعُونَ (23) وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَيُحْيِي بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (24) وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ تَقُومَ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ بِأَمْرِهِ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِنَ الْأَرْضِ إِذَا أَنْتُمْ تَخْرُجُونَ (25) وَلَهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ كُلٌّ لَهُ قَانِتُونَ (26) وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَى فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(27)"

''Nitori naa e maa se afomo fun Olohun nigba ti e ba wa ni ale ati nigba ti e ba wa ni owuro \\ Ati pe ti Re ni ope ninu sanmo ati ile, (e se afomo fun Un) ni asale ati ni igba ti osan ba pon ba yin \\ O ma n yo alaaye jade lati ara oku O si ma nyo oku jade lati ara alaaye O si ma n ta ile ji leyin ti o ti ku. Bayen ni A oo se mu eyin naa jade ninu awon amin Re pe, O seda yin lati ara yerupe leyin naa ni eyin di abara ti e ntuka (si ori ile) \\ Ati pe o n be ninu awin Re pe, O da awon aya yin fun yin lati ara yin ki e le ba ma ri ifayabale lodo won O si se ife ati ike si aarin yin. Dajudaju awon ami n be ninu eyi fun awon eniyan ti o nronu \\ O si tun n be ninu awon ami Re, dida sanmo ati ile ati yiyato si ara won awon ede ati awo awo yin. Dajudaju awon arisami n be ninu eyi fun awon onimimo \\ Ati pe o n be ninu ami Re oorun yin ti oru ati ti osan ati wiwa ti e nwa oore Re. dajudaju ami n be ninu eyi fun awon eniyan ti o ngbo (oro) \\ O si n be ninu ami Re fifi manamana han yin niti iberu ati ireti, ati pe O ma nso mi kale lati oke sanmo leyin naa A maa fi ji ile leyin ti o ti ku. Dajudaju awon n be ninu eyi fun awon eniyan onilakaye \\ Ati pe o n be ninu ami Re diduro sanmo ati ile pelu ase Re. leyin naa nigba ti O ba pe yin ni pipe eekan naa nigba naa eyin yoo jade lati inu ile \\ Ati pe ti Olohun ni awon eni ti n be ninu sanmo ati ninu ile gbogbo won ni o tele (ti Olohun) \\ Ati pe Oun ni O n bere eda dida leyin naa yoo tun un da ati pe eleyi rorun ju lo fun Un. Ati pe ti Re ni apejuwe ti o ga ju lo ninu sanmo ati ile; Oun si ni Alagbara, Ologbon'.' Q 30: 17-27

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ (54)

''Ati oorun ati osupa ati irawo ni O teri won ba pelu ase Re, kiye si i, ti Re ni ideda ati ase. Ibukun ni fun Olohun Oluwa gbogbo eda.'' Q 7:54.

2 - Lara awon eri fun bibe Olohun tun ni bi omoniyan se je ohun iyalenu nibi ideda re ati igunrege nibi ona ti Olohun gba to o, pelu ohun ti Olohun da si lara ninu agbara ati ikapani. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَفِي الْأَرْضِ آيَاتٌ لِلْمُوقِنِينَ (20) وَفِي أَنْفُسِكُمْ أَفَلَا تُبْصِرُونَ (21)

''Awon ami wa ni ori ile fun awon eni ti won alamodaju \\ (Ami wa) ninu ara yin paapaa, eyin ko woye ni?'' Q 51:20-21

3 - Awon eranko pelu, eyi ti omoniyan n se anfaani orisirisi lara re nibi jije, mimu, wiwo ati gigun re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِنَّ لَكُمْ فِي الْأَنْعَامِ لَعِبْرَةً نُسْقِيكُمْ مِمَّا فِي بُطُونِهِ مِنْ بَيْنِ فَرْثٍ وَدَمٍ لَبَنًا خَالِصًا سَائِغًا لِلشَّارِبِينَ (66) وَمِنْ ثَمَرَاتِ النَّخِيلِ وَالْأَعْنَابِ تَتَّخِذُونَ مِنْهُ سَكَرًا وَرِزْقًا حَسَنًا إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَةً لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (67) وَأَوْحَى رَبُّكَ إِلَى النَّحْلِ أَنِ اتَّخِذِي مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا وَمِنَ الشَّجَرِ وَمِمَّا يَعْرِشُونَ (68) ثُمَّ كُلِي مِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ فَاسْلُكِي سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلًا يَخْرُجُ مِنْ بُطُونِهَا شَرَابٌ مُخْتَلِفٌ أَلْوَانُهُ فِيهِ شِفَاءٌ لِلنَّاسِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَةً لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (69)

''Ati pe ariwoye wa fun yin lara awon eran osin. A n fun yin mu ninu ohun ti n be ninu ikun re lati ara boto inu agbedu ati eje, wara mimo ti n lo gaaraga ni ofun awon ti n mu – un // Ati pe lati ara awon eso dabinu ati eso ajara ni e ti n se oti ati ohun amu – soro to dara. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo to ni laakaye // Oluwa re si fi mo kokoro oyin pe: ”Maa kole sinu apata ati igi ati ohun ti (awon eniyan) mo ga. // Leyin naa, maa je lara gbogbo eso, ki o si maa to awon oju ona Oluwa pelu iteriba. Ohun mimu ti awo re yato sira won yoo ma jade lati inu (Kokoro oyin). Iwosan ni fun awon eniyan. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo to ni arojinle.'' Q 16:66-69.

4 - Lara awon eri fun bibe Olohun naa tun ni awon ewe be ati awon igi pelu awon irugbin ti Olohun da ni orisirisi aworan ati ni orisirisi awo, eyi ti omoniyan n se anfaani lara re nibi jije, mimu, fifi ko ile ati fifise iwosan. Olohun ti ola re ga so bayi pe: 

"وَهُوَ الَّذِي مَدَّ الْأَرْضَ وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنْهَارًا وَمِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ جَعَلَ فِيهَا زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (3) وَفِي الْأَرْضِ قِطَعٌ مُتَجَاوِرَاتٌ وَجَنَّاتٌ مِنْ أَعْنَابٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَى بِمَاءٍ وَاحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَى بَعْضٍ فِي الْأُكُلِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (4)

''Oun ni Eni ti O te ile (perese), O si fi awon apata to duro gbagidi sinu ile ati awon odo sisan. Ati gbogbo awon orisirisi eso O se ni onimeji tako tabo. O n fi oru bo osan loju. Dajudaju awon ami n be ninu eleyi fun awon eniyan ti nronu jinle \\ O tun wa ninu ilea won abala – abala ile (oniran – anran) to wa nitosi ara won ati awon ogba oko Inab ati irugbin ati igi dabinu eleka ati alaileak. Omi kan naa sin i won n fun won (mu), ti A nfun won mu ninu omi kanna, A si da apakan lola ju apakan lo nibi jije. Dajudaju arikogbon n be ninu iyen fun awon eniyan ti won ni laakaye.'' Q 13:3-4.

  5- Lara awon eri fun bibe Olohun tun ni awon eda orisirisi wonyi ti won n rin ni ori ile, pelu bi gbogbo won se wa ni orisirisi ipin, aworan ati iroyin. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

خَلَقَ السَّمَاوَاتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا وَأَلْقَى فِي الْأَرْضِ رَوَاسِيَ أَنْ تَمِيدَ بِكُمْ وَبَثَّ فِيهَا مِنْ كُلِّ دَابَّةٍ وَأَنْزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَنْبَتْنَا فِيهَا مِنْ كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ (10) هَذَا خَلْقُ اللَّهِ فَأَرُونِي مَاذَا خَلَقَ الَّذِينَ مِنْ دُونِهِ بَلِ الظَّالِمُونَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ (11)

''O da awon sanmo laini opo ti e le ri, O si ju awon apata to duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le maa mi mo yin lese, O fon orisirisi eranko ka si ori ile, O tun so omi kale lati Sanmo, asi fi n mu orisirisi eso alaponle mu jade lati inu ile. \\ Eyi ni eda ti Olohun, nitori naa e fi han mi oun ti awon miiran leyin re da ni eda Nse ni awon alabosi wa ninu isina ponmn bele.'' Q 31:10-11

6-  Lara awon eri fun bibe Olohun tun ni eto iyanu lori imaa bisi imaa resi eyi ti o gunrege ti ko ni abuku rara laarin gbogbo eda patapata, eyi ti o si je okunfa fun imaa tesiwaju isemi ati iduro deedee ile aye yi, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَاللَّهُ خَلَقَ كُلَّ دَابَّةٍ مِنْ مَاءٍ فَمِنْهُمْ مَنْ يَمْشِي عَلَى بَطْنِهِ وَمِنْهُمْ مَنْ يَمْشِي عَلَى رِجْلَيْنِ وَمِنْهُمْ مَنْ يَمْشِي عَلَى أَرْبَعٍ يَخْلُقُ اللَّهُ مَا يَشَاءُ إِنَّ اللَّهَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (45)

''Olohun se eda gbogbo abemi lati inu omi. O wa ninu won, O wa ninu won, eyi n fi ese meji rin o wa ninu won eyi ti o n fi ese merin rin. Olohun n se eda ohun ti o ba fee. Dajudaju Olohun ni Alagbara lori gbogbo sanmo.'' Q 24:45.

7-  Lara awon eri fun bibe Olohun tun ni ipin ije imu (arisiki) eyi ti ko ni ekeji ati ifini lokan bale lori re eyi ti Olohun se fun gbogbo eda patapata, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا مِنْ دَابَّةٍ فِي الْأَرْضِ إِلَّا عَلَى اللَّهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُبِينٍ (6)"

''Ko si eda kan ti o wa ni ori ile ayafi ki ipese (ije imu) re maa be ni odo Olohun ati pe O si mo ibugbe re (ni aye) ati ibupamo re (sile ti o maa ku si), gbogbo re n be ninu (akosile) ti o han.'' Q 11:6.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

وَكَأَيِّنْ مِنْ دَابَّةٍ لَا تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ (60)"

''Meloo meloo ninu awon eranko ni ko le da bukata ije imu re gbe ti, Olohun si n se ije – imu fun ohun ati eyin naa. Oun ni Olugboro, Olumo.'' Q 29:60.

Olohun ti mimo n be fun se alaye pe dajudaju gbogbo ohun ti n be ninu ile aye yi ni eda ni Oun da ni meji meji ti won si je idakeji ara won, fun apere: sanmo ati ile, oru ati osan, isemi ati iku, oriire ati oriburuku, oorun ati osupa, ohun ti duro ti ko mira ati ohun ti o duro lojukan, tutu ati gbigbona, daradara ati laburu, aigbagbo ati igbagbo, gege bee naa ni nibi awon eda eranko ati awon ohun ogbin ati awon nnkan miiran ninu awon ohun ti a mo ati awon ohun ti a ko mo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمِنْ كُلِّ شَيْءٍ خَلَقْنَا زَوْجَيْنِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ (49)

''Ati pe gbogbo sanmo ni A da ni orisi meji meji ki e le ba maa ranti lati lo isiti.'' Q 51:49.

Dajudaju imaa ronu si awon eda Olohun wonyi maa n se alekun imo nipa Adeda Eni ti mimo n be fun ti ola Re ga. Bakan naa tun ni pe imaa ronu si awon nnkan wonyi je okan ninu iroyin awon onilakaye eniyan, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجْنَا بِهِ ثَمَرَاتٍ مُخْتَلِفًا أَلْوَانُهَا وَمِنَ الْجِبَالِ جُدَدٌ بِيضٌ وَحُمْرٌ مُخْتَلِفٌ أَلْوَانُهَا وَغَرَابِيبُ سُودٌ (27) وَمِنَ النَّاسِ وَالدَّوَابِّ وَالْأَنْعَامِ مُخْتَلِفٌ أَلْوَانُهُ كَذَلِكَ إِنَّمَا يَخْشَى اللَّهَ مِنْ عِبَادِهِ الْعُلَمَاءُ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ (28)

''Ire ko ha ri (i) ni pe dajudaju Olohun lo so omi kale lati sanmo? A si fi mu awon eso ti awqo re yato sira won jade Ati pe ninu awon oke ojuona funfun ati pupa ti awo re yato sira won. Pelu alawo dudu kirikiri won wa ninu awon apata. wa ni funfun ati pupa ti awo won yato si ara won ati awon ti o dudu kirikiri \\ Ati pe o wa ninu awon eniyan, awon sanmo elemi ati awon eran – osin ti awo won yato sira won, gege bi (awo eso ati apata) won yen (se yato sira won). Owo awon ti n beru Olohun ninu awon erusin Re ni awon ti won mo (pe Olohun ni Alagbara lori gbogbo sanmo). Dajudaju Olohun ni Alagbara Alaforijin.'' Q 35:27-28.

Ko ti salaye apakan imo ipile re ti o sit i fi apakan imo re pamo eda Kannkan ni ile aye yi ti Olohun (Oba mimo oba to ga ju lo) Ko ti salaye apakan imo ipile re ti o sit i fi apakan imo re pamo eda Kannkan ni ile aye yi ti Olohun (Oba mimo oba to ga ju lo) pe:

سُبْحَانَ الَّذِي خَلَقَ الْأَزْوَاجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنْبِتُ الْأَرْضُ وَمِنْ أَنْفُسِهِمْ وَمِمَّا لَا يَعْلَمُونَ (36)

''Mimo fun Eni ti O se eda gbogbo nnnkan ni orisirisi (meji meji) ninu ohun ti ile n mu jade, ati ninu awon emi won ati ninu ohun ti won ko mo.'' Q 36:36.

Ko si iyemeji nibi wi pe agbara kan n be ti o se eda awon nnnkan wonyi ti o n mojuto won ti o si ndari won.

Okan ninu nnkan meta ti ko ni ekerin pere ni o le je ironu omoniyan lori awon eda wonyi:

Alakooko: Ninu ki o je pe ile aye yi pelu bi o se wa leto leto ni ona ti o gunrege ni o seda ara re funra re, iru ero bayi je eyi ti ko rorun ki o ri bee rara ko si fesemunle, nitori pe gbogbo ohun ti o ba je eda ni o gbodo ni adeda ti o da a.

Elekeeji: ki o je pe ile aye yi je ohun ti nnkankan da ati pe ohun ti o da ile aye naa wa lati inu re (ile aye). Iru oro bayi tako laakaye ko si se e maa so jade beeni ko si ba laakaye mu rara, nitori pe ko seese fun nnkankan lati da ara re siwaju ki o to maa semi.

Eleeketa: ki o je pe ile aye yi ati gbogbo oun ti n be ninu re je eda lati owo adeda kan ti ko si ninu ile aye naa ti o si yato gedengbe si (ile aye), eleyi tii se Olohun Oluwa gbogbo agbaye patapata. Eleyi si ni ohun ti awon musulumi onigbagbo ododo ni igbagbo si, sugbon awon ti o yato si won ninu awon ti ko gbagbo ninu bibe Olohun wa ninu iyemeji ti ko ni ekeji. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

"أَمْ خُلِقُوا مِنْ غَيْرِ شَيْءٍ أَمْ هُمُ الْخَالِقُونَ (35) أَمْ خَلَقُوا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بَلْ لَا يُوقِنُونَ (36) أَمْ عِنْدَهُمْ خَزَائِنُ رَبِّكَ أَمْ هُمُ الْمُصَيْطِرُونَ (37)"

''Abi won da won lasan laisi Aseda? Abi awon ni won da ara won \\ Abi awon ni won da awon ati ile ni? Beetieko won ko ni imo amodaju ni \\ Abi pepe oro ti Oluwa re n be ni odo won ni? Abi awon yoo bori wa?'' Q 52:35-37.

ADOJUKO ADAMO IPILE: Dajudaju emi omoniyan je eyi ti Won da ni ipile lori imaa ni igbonmo ati gbigba pe oun ni enikan ti o je adeda oun ati ile aye ti a wa yi, eleyi si ni awon onimimo maa n pe ni '' Adamo Esin '' Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا فِطْرَتَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللَّهِ ذَلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ (30)

''Nitori naa da oju re ko esin ododo, ki o duro deede Adamo Olohun da mo awon eniyan (ni esin Islam) ko si le si iyipada fun esin Olohun. Iyen ni esin to feserinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo.'' Q 30:30.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:

"مَا مِنْ مَوْلُودٍ إِلَّا يُولَدُ عَلَى الفِطْرَةِ، فَأَبَوَاهُ يُهَوِّدَانِهِ أَوْ يُنَصِّرَانِهِ، أَوْ يُمَجِّسَانِهِ، كَمَا تُنْتَجُ البَهِيمَةُ بَهِيمَةً جَمْعَاءَ، هَلْ تُحِسُّونَ فِيهَا مِنْ جَدْعَاءَ، ثُمَّ يَقُولُ أَبُو هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ: {فِطْرَةَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا} [الروم: 30] الآيَةَ" متفق عليه

''Kosi omo asesebi kan tiwon maa bi ayafi ki won bi si ori ipile (Islam), sugbon awon obi re mejeeji ni won yoo so di elesin Yehuudi tabi elesin Nasara (Kirisiteni) tabi elesin majuusi (bona bona), bi o se je pe eranko elese merin maa nbi omo (eranko elese merin) ni pipe, nje e wa ri ki o je alaabo ara (nigba ti won bi) bi? Leyin naa ni Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) wa ka oro Olohun ti o so bayi pe: ''Adamo ti Olohun eyi ti O fi da omoniyan'' Q 30:30'' (Al Bukhari ati Muslim).

……nje e wa ri ki o je alaabo ara (nigba ti won bi) bi? Tumo si pe omoniyan ni o ma nso igba d'ogbun igba ko gbun rara.

Koda nigba ti adamo yi ba kuro lori ipile re (ti o gun), e o si ri ti yoo maa bukata si agbara kan ti yoo maa ba gbo awon bukata, ti yoo si maa pada si odo re nigba ti ifun pinpin ba de baa tabi ti adanwo ba sele si. E o ri olutako bibe Olohun tabi eni ti ko ni igbagbo si Olohun nigba ti aisan, adanwo, oun ti okan ko tabi ajalu kan ba sele si ti yoo gbe oju ati owo re soke si ogangan sanmo, lai fura, ti yoo si maa so pe; Ire Olohun o '' ti yoo si maa se afirinle bibe agbara kan ti o kanpa, ti o si ni ikapa lati yo oun ninu oun ti oun wa naa. Ododo ni oro Olohun ti O so pe: 

"وَإِذَا مَسَّ الْإِنْسَانَ الضُّرُّ دَعَانَا لِجَنْبِهِ أَوْ قَاعِدًا أَوْ قَائِمًا فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُ ضُرَّهُ مَرَّ كَأَنْ لَمْ يَدْعُنَا إِلَى ضُرٍّ مَسَّهُ كَذَلِكَ زُيِّنَ لِلْمُسْرِفِينَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (12)

''Nigba ti inira ba de ba omoniyan, yoo maa ke pe Wa, lori idubulere tabi ni ijokoo tabi ni iduro, sugbon ni igba ti A ba mu inira re kuro fun un, yoo taku (sori aigbagbo) gegebi eni ti ko pe Wa si inira ti o ba a. Bayi ni A se ni oso fun awon alakojo eniyan ohun ti won n se nise.'' Q 10:12.

IPENIJA AL KURANI: Al kurani Alaponle n pe gbogbo eda patapata nija, yala lapapo ni tabi ni eyo kookan, lori ki won se eda kan pere ti emi yoo si maa be ni ara re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَا أَيُّهَا النَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٌ فَاسْتَمِعُوا لَهُ إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ لَنْ يَخْلُقُوا ذُبَابًا وَلَوِ اجْتَمَعُوا لَهُ وَإِنْ يَسْلُبْهُمُ الذُّبَابُ شَيْئًا لَا يَسْتَنْقِذُوهُ مِنْهُ ضَعُفَ الطَّالِبُ وَالْمَطْلُوبُ (73)

''Eyin eniyan, A fi apejuwe kan lele, nitori naa e tete si i. Dajudaju awon ohun ti e n pe leyin Olohun ko le da esinsin kan, koda ki won parapo lati se e. Ti esinsin ba si gbe nnkankan lodo won, won ko le gba a lowo re O le ni. Eni ti ntoro nnkan ati eni ti won ntoro lodo re.'' Q 22:73.

Eleyi ri bee nitori pe dajudaju emi gbogbo eda ko je dada ayafi pelu ase Olohun nikan soso, bakan naa ko si eni ti o mo paapaa emi yi ayafi Olohun nikan soso. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الرُّوحِ قُلِ الرُّوحُ مِنْ أَمْرِ رَبِّي وَمَا أُوتِيتُمْ مِنَ الْعِلْمِ إِلَّا قَلِيلًا (85)

''Ati pe won yoo bi o leere nipa emi. So pe: emi n be ninu ase Oluwa mi, ati pe A ko fun yin ni imo ayafi die.'' Q 17:85.

Koda won tun le nibi ki won da nnkan eyo kan soso ti ko lemi, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

قال الله عز وجل: "ومن أظلم ممن ذهب يخلق كخلقي فليخلقوا ذرّةً أو ليخلقوا حبةً أو شعيرةً" متفق عليه.

”Olohun ti aponle ati gbi gbongbon n be fun so pe: kosi eni ti o je alabosi to eni ti o da eda ti o jo temi. (ti won ba lagbara bee) ki won da awurebe tabi jero tabi okababa.'' (Al Bukhari ati Muslim).

IKAGARA OMONIYAN NIBI NINI IKAPA LORI ETO ILE AYE YII: Eleyi je eri pataki lori bibe Adeda ti o je Oludari awon eto inu re, Olohun ti ola Rega so bayi pe:

أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِي حَاجَّ إِبْرَاهِيمَ فِي رَبِّهِ أَنْ آتَاهُ اللَّهُ الْمُلْكَ إِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّيَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا أُحْيِي وَأُمِيتُ قَالَ إِبْرَاهِيمُ فَإِنَّ اللَّهَ يَأْتِي بِالشَّمْسِ مِنَ الْمَشْرِقِ فَأْتِ بِهَا مِنَ الْمَغْرِبِ فَبُهِتَ الَّذِي كَفَرَ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (258)

''Se Iwo ko ha w'oye nipa eni ti o ba (Anabi) Ibraheem jiyan nipa Oluwa re, nitori pe Olohun ti fun un ni ijoba, nigba ti Ibroohim wi pe: Oluwa mi ni Eni ti n so ni di alaaye, o sin so ni di oku, o si wi pe; Emi naa n so ni di alaaye. Mo si n so ni di oku. (Anabi) Ibroohim. So pe: O daa, dajudaju Olohun n mu oorun wa lati ibuyo. Mu un wa nigba naa lati iburo. Bayi ni A ko idaamu ba eni ti ko gbagbo naa. Olohun kii to awon alabosi sona.'' Q 2:258.

NINU EYI TI O TUN JE OKAN PATAKI NINU AWON ERI ATI ITOKA LORI BIBE OLOHUN ENI TI MIMO N BE FUN, OUN NI BI O SE PE GBOGBO OMONIYAN PATAPATA NIJA LORI KI WON MU IRU (OHUN TI O JO) AL KURANI WA, EYI TI O JE OPIN GBOGBO TIRA TI O WA LATI OKE SANMO (NI ODO OLOHUN). Eleyi je ipenija ti yoo maa lo titi di ojo igbende. Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

قُلْ لَئِنِ اجْتَمَعَتِ الْإِنْسُ وَالْجِنُّ عَلَى أَنْ يَأْتُوا بِمِثْلِ هَذَا الْقُرْآنِ لَا يَأْتُونَ بِمِثْلِهِ وَلَوْ كَانَ بَعْضُهُمْ لِبَعْضٍ ظَهِيرًا (88)

''So pe: Ti awon eniyan ati alujannu ba para po lati mu iru Al kurani yi wa, won ko le mu iru re koda ki apa kan won ran apa keji lowo.'' Q 17:88.

Enikeni ti o ba n se iyemeji si bibe Olohun tabi se iyemeji si ije ojise Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki o yara sise lori ipeni nija yi ki o si mu iru Al kurani wa. Eyi ti o daju ni wi pe awon ti won je elede larubawa ti won si dalawon ninu eda lapapo, ti won on je iran larubawa, ni awon ti Al Kurani so kale pelu ede won, won gbiyanju lati se bee sugbon won ko se aseyori lori re pelu bi won se daniyan ti o lagbara lati doju ipeni nija naa bole, bakan naa ni ipeni nija Al Kurani yi tun de odo awon alatako awon ti won nro pe oro eniyan lasan ni Al Kurani naa, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ قُلْ فَأْتُوا بِعَشْرِ سُوَرٍ مِثْلِهِ مُفْتَرَيَاتٍ وَادْعُوا مَنِ اسْتَطَعْتُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ (13)

''Abi won n wi pe; o da a se fun ara re ni. Nigba naa naa so pe: Eyin e mu ogba oro (surah) mewa iru re wa niti adase, ki e si pe eni ti e ba ni agbara lati pe leyin Olohun (fun iranlowo) ti eyin ba je olododo.'' Q 11:13.

Olohun ti ola Re ga tun so ni aaye bi bayi pe:

وَإِنْ كُنْتُمْ فِي رَيْبٍ مِمَّا نَزَّلْنَا عَلَى عَبْدِنَا فَأْتُوا بِسُورَةٍ مِنْ مِثْلِهِ وَادْعُوا شُهَدَاءَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ (23)

''Bi e ba si wa ninu iyemeji nipa ohun ti Awa so kale fun erusin wa, a je wi pe, e mu ogba oro (surah) kan wa ti yio da bii re ki e si pe awon eleri yin ti kii se Olohun bi eyin ba je olotito.'' Q 2:23.

Dajudaju Al_Kurani yi oro Olohun ti a so kale nii se, ti kii si se adapa iro, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا كَانَ هَذَا الْقُرْآنُ أَنْ يُفْتَرَى مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلَكِنْ تَصْدِيقَ الَّذِي بَيْنَ يَدَيْهِ وَتَفْصِيلَ الْكِتَابِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ (37)

''Al kurani ki i se ohun ti o se e dahun (lati odo elomiiran) leyin Olohun, sugbon o je ifidi - ododo mule nipa eyiti n be siwaju re ati alaye nipa awon Tira naa, ko si iyemeji nipa re, lati odo Oluwa gbogbo eda (ni o ti wa).'' Q 10:37.

Nitori pe ti o ba jepe oro omoniyan lasan ni, ko fa foju han gbangba bee latara titako ti awon ese oro (aayah) re yoo maa tako ara won, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ الْقُرْآنَ وَلَوْ كَانَ مِنْ عِنْدِ غَيْرِ اللَّهِ لَوَجَدُوا فِيهِ اخْتِلَافًا كَثِيرًا (82)

''Won ko ha ni ronu nipa Al Kurani ni? Bi o ba je pe o wa lati odo elomiiran yato si Olohun, won ko ri iyapa oro (itakora eni) ninu re.'' Q 4:82.

Bayi, ibi ti a o ti bere oro wa nipa ibere ideda ati opin re naa ni oro Olohun ti o so pe:

اللَّهُ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ (62) لَهُ مَقَالِيدُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ

''Olohun ni Eleda gbogbo nnkan ati pe Oun si ni Oluso gbogbo nnkan // Tire ni kokoro (oro) awon sanmo ati ile.'' Q 39:62-63.

 

 

AWON EDA AKOKO NINU AGBAYE TI A RI YI

Niwonba igba ti o je wi pe imo omoniyan ati akiyesi re ko koja ile aye yi ti o ti n semi ti o si nri i, nitori idi eyi ko ni bukata si ki o ni imo oun ti n be leyin eleyi ayafi eyi ti yoo ba je okunfa lati mo amodaju fun nipa titobi Oludeda re ti yoo si je ki o ri iyonu Re ati ti yoo mu wo ogba idera (Al jannah). Nitori eleyi ni Oluwa wa ti ola Re ga se ran awon Ojise Re lati igba de igba, ti O si fi die yewon ninu awon imo ohun ti o pamo ni ibamu si ohun ti imo re yoo se won ni anfaani.

Niwonba igba ti o jepe lakaye omoniyan ko ni ikapa lati mo oun ti o wa leyin gaga ti o doju ko, eleyi je ki o yewa lai siyemeji pe lakaye re ko le gbe oun ti o wa leyin ile aye, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

الَّذِي خَلَقَ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ طِبَاقًا مَا تَرَى فِي خَلْقِ الرَّحْمَنِ مِنْ تَفَاوُتٍ فَارْجِعِ الْبَصَرَ هَلْ تَرَى مِنْ فُطُورٍ (3) ثُمَّ ارْجِعِ الْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنْقَلِبْ إِلَيْكَ الْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ (4)

''Oun ni Eni ti O da sanmo meje ni ipele (kan lori) ipele (kan), Iwo ko le ri aigunrege kan lara eda (Oba) Ajoke aye. Nitori naa tun wo o l'awo tun wo: Nje o le ri ibikan ti o ti yinje bi? \\ Leyin naa ki o tun wo o l'awo ton wo leemeji si, ki oju re pada si odo re pelu iyipere. O si maa kaare.'' Q 67:3-4.

 

SISEDA SANMO ATI ILE ATI AWON OHUN TI N BE LAARIN AWON MEJEEJI

Olohun ti ola Re ga so pe:

وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ وَيَوْمَ يَقُولُ كُنْ فَيَكُونُ قَوْلُهُ الْحَقُّ وَلَهُ الْمُلْكُ يَوْمَ يُنْفَخُ فِي الصُّورِ عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ وَهُوَ الْحَكِيمُ الْخَبِيرُ (73)

''Oun si ni Eni ti O seda sanmo ati ile fun idi Pataki. Ati pe: (ranti) ojo ti (Olohun maa yi ile ati sanmo pada si nnkan miiran, o si maa so pe: Je bee, ti yio si je bee. Oro Re ododo ni, ti Re si ni ijoba naa ni ojo ti A o fon iwo. (Oun ni) Olumo ikoko ati gbangba, Oun si ni Ologbon, Oluridi ohun gbogbo.'' Q 6:73.

DIE NINU AWON EDA OLOHUN TO WA NINU SANMO ATI ILE

Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَجَعَلْنَا السَّمَاءَ سَقْفًا مَحْفُوظًا وَهُمْ عَنْ آيَاتِهَا مُعْرِضُونَ (32) وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ كُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ (33)

''Ati pe A se sanmo ni aja ni ohun ti A n so (nibi jijabo), sibesibe won si n seri kuro nibi awon ami ( ti n be loju sanmo) \\ Oun ni Eni ti O da oru ati osan ati oorun ati osupa, ikookan wa ni opopona ti n to.'' Q 21:32-33.

Olohun ti ola Rega tun so bayi pe:

أَأَنْتُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمِ السَّمَاءُ بَنَاهَا (27) رَفَعَ سَمْكَهَا فَسَوَّاهَا (28) وَأَغْطَشَ لَيْلَهَا وَأَخْرَجَ ضُحَاهَا (29) وَالْأَرْضَ بَعْدَ ذَلِكَ دَحَاهَا (30) أَخْرَجَ مِنْهَا مَاءَهَا وَمَرْعَاهَا (31) وَالْجِبَالَ أَرْسَاهَا (32) مَتَاعًا لَكُمْ وَلِأَنْعَامِكُمْ (33)

''Se eyin ni e l'agbara ju lo ni iseda abi sanmo ti (Olohun) da ? \\ Olohun gbe aja re ga soke, O si se e (ni pipe to gun rege) \\ O se oru re ni dudu, O si fa iyaleta re yo jade \\ Ati pe iyen, eyini O te ile naa perese \\ O mu omi ati irugbin re jade \\ Ati awon apata (oke) O fi idi won mule sinsin \\ Igbadun ni fun yin ati fun awon eran osin yin.'' Q 79:27-33.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

وَأَرْسَلْنَا الرِّيَاحَ لَوَاقِحَ فَأَنْزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَسْقَيْنَاكُمُوهُ وَمَا أَنْتُمْ لَهُ بِخَازِنِينَ (22)

''Ati pe A ran awon ategun ti n lati ko esujo jo. A si so omi kale lati inu sanmo, Nitori naa a fun yin mu. Eyin si ko ni e ko omi ojo jo (si oju sanmo) nfun yin mu, eyin ko ni e nko o jo.'' Q 15:22.

Orisirisi ni ategun naa ni ibamu si bi Olohun ti ola re ga se salaye re, o n be ninu re ti o je ike lati odo Olohun, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَهُوَ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ بُشْرًا بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ حَتَّى إِذَا أَقَلَّتْ سَحَابًا ثِقَالًا سُقْنَاهُ لِبَلَدٍ مَيِّتٍ فَأَنْزَلْنَا بِهِ الْمَاءَ فَأَخْرَجْنَا بِهِ مِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ كَذَلِكَ نُخْرِجُ الْمَوْتَى لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ (57)

''Oun ni Eni ti n ran ategun (ti o je) iro idunnu siwaju aanu Re titi (ategun – naa) ti yoo fi gbe esujo to wuwo, A si maa wo on losi ile ti o fi sa, nigba naa A maa fi so omi kale A si maa mu orisirisi eso jade. Bayen ni A o se mu awon oku jade nitori ki e le lo isiti.'' Q 7:57.

O n be ninu re ti o je ifiyajeni ati idiyaje lati odo Olohun, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

أَمْ أَمِنْتُمْ أَنْ يُعِيدَكُمْ فِيهِ تَارَةً أُخْرَى فَيُرْسِلَ عَلَيْكُمْ قَاصِفًا مِنَ الرِّيحِ فَيُغْرِقَكُمْ بِمَا كَفَرْتُمْ ثُمَّ لَا تَجِدُوا لَكُمْ عَلَيْنَا بِهِ تَبِيعًا (69)

''Abi eyin wa fi okan bale pe (Olohun) ko ni pada mu yin wa si (ori omi) nigba miiran ni o maa ran iji ategun si yin nigba naa. A o si ma ate yin ri (sinu omi) nitori aimoore yin? Leyin naa, eyin ko nii ri oluranlowo kan ti o ma aba yin gbesan lara wa.'' Q 17:69.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

"... فَأَصَابَهَا إِعْصَارٌ فِيهِ نَارٌ فَاحْتَرَقَتْ

''Ki ategun lile ti ina n be ninu re kolu u, ki o si jona?'' Q 2:266.

Bakanna ni Olohun ti ola Re ga tun so pe:

فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا صَرْصَرًا فِي أَيَّامٍ نَحِسَاتٍ

''Nirori naa, A ran ategun lile si won ni awon ojo buruku kan nitori ki A le je ki won to iya yepere wo ninu isemi aye yii. Iya ojo ikehin yo sat un yepere won ju lo, A o sin ii ran won lowo.'' Q 41:16.

O se eda won ni sanmo meje ati ile meje, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ وَمِنَ الْأَرْضِ مِثْلَهُنَّ يَتَنَزَّلُ الْأَمْرُ بَيْنَهُنَّ لِتَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ وَأَنَّ اللَّهَ قَدْ أَحَاطَ بِكُلِّ شَيْءٍ عِلْمًا (12)"

''Olohun ni Eni ti O da sanmo meje ati ile ni (onka). O si n so ase Re kale laarin won nitori ki e le mo pe dajudaju Olohun ni Alagbara lori gbogbo nnkan. Ati pe dajudaju Olohun fi imo ro gba yi gbogbo nnkan ka.'' Q 65:12.

Ni ipile ideda sanmo ati ile wa papo ti won le mo ara won pekipeki, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

أَوَلَمْ يَرَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ كَانَتَا رَتْقًا فَفَتَقْنَاهُمَا وَجَعَلْنَا مِنَ الْمَاءِ كُلَّ شَيْءٍ حَيٍّ أَفَلَا يُؤْمِنُونَ (21:30)

''So pe: Awon ti won saigbagbo ko ri i pe dajudaju awon sanmo Olohun ti ola Re ga salaye iye ojo ti O fi da awon sanmo ati ile pelu awn ohunkan ti o wa ninu sanmo ati ile. Olohun ti ola Re ga so pe: A si ya won si otooto, A si se gbogbo nnkan ni abemi lati inu omi? Nitori naa, se won ko nii gbagbo ni?'' Q 21:30.

Olohun ti mimo n be fun salaye iye asiko ti O fi da awon sanmo ati ile pelu awon ohun ti n be ninu won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُلْ أَئِنَّكُمْ لَتَكْفُرُونَ بِالَّذِي خَلَقَ الْأَرْضَ فِي يَوْمَيْنِ وَتَجْعَلُونَ لَهُ أَنْدَادًا ذَلِكَ رَبُّ الْعَالَمِينَ (9) وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ مِنْ فَوْقِهَا وَبَارَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَا أَقْوَاتَهَا فِي أَرْبَعَةِ أَيَّامٍ سَوَاءً لِلسَّائِلِينَ (10) ثُمَّ اسْتَوَى إِلَى السَّمَاءِ وَهِيَ دُخَانٌ فَقَالَ لَهَا وَلِلْأَرْضِ ائْتِيَا طَوْعًا أَوْ كَرْهًا قَالَتَا أَتَيْنَا طَائِعِينَ (11) فَقَضَاهُنَّ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ فِي يَوْمَيْنِ وَأَوْحَى فِي كُلِّ سَمَاءٍ أَمْرَهَا وَزَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِمَصَابِيحَ وَحِفْظًا ذَلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ (12)

''So pe: Nje dajudaju eyin n saigbagbo ninu Eni ti O da ile fun ojo meji, e si n so (eda Re) di orogun fun – un? Iyen sin i Oluwa gbogbo eda // O si fi awon apata sinu ile, won si je oke fun ile, o fi ibukun sinu re. o si pin awon ounje (ori ile fun eda) laarin ojo merin, (Awon ojo naa) dogba (sira won) fun awon ti won ba fe beere (nipa re) // Leyin naa, O gbero iseda sanmo, ti o wa ni eefin, O si so fun ohun ati ile pe: ”E wa bi e fe tabi e ko”. Awon mejeeji so pe: ”Awa wa pelu ifinnu – findo”O si pari (iseda) re si sanmo meje fun ojo meje. O si fi ise sanmo kookan ranse sinu re. A si fi awon atupa (irawo) se sanmo ile aye ni oso ati aabo (fun – un). Iyen ni eto Alagbara, Olumo.'' Q 41:9-12.

 

ISEDA AWON MALAIKA

Eda kan ninu awon eda Olohun ni awon Malaika je, O dawon lati ara imole. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

خلقت الملائكة من نور، وخلق الجان من مارج من نار، وخلق آدم مما وصف لكم” رواه مسلم.

''Won da awon Malaika lati ara imole, Won si da awon alijannu lati ara ejijo ina, Won si da Adamo lati ara ohun ti won ti salaye re fun yin (yerupe).'' (Muslim).

Olohun da won fun awon ise orisirisi ti O gbe fun won, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا مِنَّا إِلَّا لَهُ مَقَامٌ مَعْلُومٌ (164) وَإِنَّا لَنَحْنُ الصَّافُّونَ (165) وَإِنَّا لَنَحْنُ الْمُسَبِّحُونَ (166)

''Ko si eni kan ninu (awon molaaika) afi ki o ni ibuduro ti Olohun ti nimo nipa re // Dajudaju awa si to ni owoowo // Ati pe dajudaju awa n se afomo (fun Olohun).'' Q 37:164-166.

Olohun ti ola Re ga daruko awon kan ninu won, gegebi Jibirilu, Mikaila ati Isirafila, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

مَنْ كَانَ عَدُوًّا لِلَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَرُسُلِهِ وَجِبْرِيلَ وَمِيكَالَ فَإِنَّ اللَّهَ عَدُوٌّ لِلْكَافِرِينَ (98)

''Eniyowu ti o ba je ota fun Olohun ati awon Malaika Re, ati awon Ojise Re ati Jibirilu ati Mikaila. (onitoun ti di alaigbagbo) Dajudaju Olohun je ota fun awon alaigbagbo.'' Q 2:98.

Malaika Jibirila ni ti e (Olohun ki o yonu si) je eni ti o maa nmu waayi (oro Olohun) wa fun awon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o maa ba won) ki won le fi jise fun awon ti won ran won si. olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِنَّهُ لَتَنْزِيلُ رَبِّ الْعَالَمِينَ (192) نَزَلَ بِهِ الرُّوحُ الْأَمِينُ (193) عَلَى قَلْبِكَ لِتَكُونَ مِنَ الْمُنْذِرِينَ (194)

''Dajudaju eyi (Al Kurani) ni imisi ti o so kale lati odo Oluwa gbogbo eda \\ Emi ododo (Jibiril) ni o so o kale \\ Sinu okan re ki o le ba je okan ninu awon olukilo.'' Q 26: 192-194.

Mikaila n tie (Olohun ki o yonu si) je alamojuto riro ojo ati irugbin, Israfilu (Olohun ki o yonu si) si je alamojuto oro fere fifon sinu iwo ni eemeta,

 fifon iberu ati ipaya, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَصَعِقَ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ..."

''Ati pe A o fon fere sinu iwo, awon ti o wa ninu sanmo ati awon ti o wa ni ori ile, won yoo si daku ...” Q 39:68.

 Fifon ti idaku ati igbende, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَصَعِقَ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ إِلَّا مَنْ شَاءَ اللَّهُ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخْرَى فَإِذَا هُمْ قِيَامٌ يَنْظُرُونَ (68)

''Ati pe A o fon fere sinu iwo, awon ti o wa ninu sanmo ati awon ti o wa ninu ile, won yoo si daku, ayafi awon ti Olohun ba fe. Leyin naa A o tun fon ni eekeji, nigba naa ni won yoo dide ti won yoo si maa wo sun un.'' Q 39:68.

Ninu won tun ni Malaika iku ati awon asomogbe (omoleyin) re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

وَهُوَ الْقَاهِرُ فَوْقَ عِبَادِهِ وَيُرْسِلُ عَلَيْكُمْ حَفَظَةً حَتَّى إِذَا جَاءَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ تَوَفَّتْهُ رُسُلُنَا وَهُمْ لَا يُفَرِّطُونَ (61) ثُمَّ رُدُّوا إِلَى اللَّهِ مَوْلَاهُمُ الْحَقِّ أَلَا لَهُ الْحُكْمُ وَهُوَ أَسْرَعُ الْحَاسِبِينَ (62)

''Oun naa ni Olubori ti O tayo awon eru Re, Oun si ni O ma nran awon oluso si yin titi di igba ti iku yoo fi wa ba enikookan yin, ti iran se Wa yoo fi gba emi re, awon ti won ki njafara (lati se oun ti A ba pawon lase re) \\ Leyin naa A o dawon pada si odo Olohun Oluwa won, (Oba) Ododo Oun naa ni O yara ju awon onisiro lo.'' Q 6:61-62.

Ninu won tun ni awon ti won gbe ali arasi (aga ola Olohun) lowo ati awon ti n be ni ayika won ninu awon Malaika alasunmo, Olohun ola Re ga so pe:

لَنْ يَسْتَنْكِفَ الْمَسِيحُ أَنْ يَكُونَ عَبْدًا لِلَّهِ وَلَا الْمَلَائِكَةُ الْمُقَرَّبُونَ

''Al Masihu (Anabi Isa) ko se ikorira lati je olujosin fun Olohun ati awon Malaika ti won sunmo Olohun.'' Q 4:172.

Ninu won tun ni awon ti n se amojuto ogba idera (Al Jannah), ninu won tun ni awon ti n se amojuto ina, Olohun ti ola Re ga so pe:

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا قُوا أَنْفُسَكُمْ وَأَهْلِيكُمْ نَارًا وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ عَلَيْهَا مَلَائِكَةٌ غِلَاظٌ شِدَادٌ لَا يَعْصُونَ اللَّهَ مَا أَمَرَهُمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ (6)

''Eyin ti e gbagbo ni ododo, e so ara yin ati awon ara ile yin kuro nibi (iya) ina, eyiti o jepe awon eniyan ati awon okuta ni yoo je ikona re, awon Malaika ti o ni ipa ati agbara ni oluse re, won kii yi ase Olohun ti O ba pa fun won pada, won a si maa mu ase ti A ba pa fun won se.'' Q 66:6.

O tun n be ninu won awon ti o jepe ojuse won ni siso awon eda, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

لَهُ مُعَقِّبَاتٌ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ يَحْفَظُونَهُ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ

''Awon oluso (Malaika) n be fun un ni iwaju re ati ni eyin re ti won nso o nibi ase Olohun ...'' Q 13:11.

O tun wa ninu won awon ti won je alamojuto ise awon eda, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَافِظِينَ (10) كِرَامًا كَاتِبِينَ (11) يَعْلَمُونَ مَا تَفْعَلُونَ (12)

''Dajudaju awon oluso (ise yin) n be lodo yin \\ Awon alakosile ti won ni ibukun \\ Ti won mo ohun ti e n se ni ise.'' Q 82:10-12.

Olohun da won nitori ki won le maa se ijosin fun Un, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَنْ عِنْدَهُ لَا يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِهِ وَلَا يَسْتَحْسِرُونَ (19) يُسَبِّحُونَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ لَا يَفْتُرُونَ (20)

''Ti Olohun ni gbogbo eni ti n be ni sanmo ati ile, ati awon ti n be ni odo Re ti won ko si n se igberaga tayo ijosin fun-Un, ti agara kii da won \\ Won a maa se afomo l'oru ati l'osan ti won ko si nja nibi sise re.'' Q 21:19-20.

Enikan ko mo ounka won ayafi Olohun ti O da won, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكْرَى لِلْبَشَرِ (31)

''Ko si eni ti o mo omo ogun Oluwa re ayafi Oun naa (ni o mo on). Ko je nnkankan ju iranti lo fun awon eniyan.'' Q 74:31.

Enikeni ti o ba fe lati mo alekun nipa oro awon Malaika ki o lo sinu awon iwe ti won ko lati salaye kikun nipa won ati awon ojuse enikookan won ni ibamu si Al-Kurani ati sunnah (oro Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba a)).

 

IDEDA ALIJANNU

Ninu awon eda Olohun ti o pamo ni alijannu, Olohun da won nitori ati maa se ijosin fun Un, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنْسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ (56) مَا أُرِيدُ مِنْهُمْ مِنْ رِزْقٍ وَمَا أُرِيدُ أَنْ يُطْعِمُونِ (57) إِنَّ اللَّهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ (58)

''Ati pe Emi ko se eda alijannu ati eniyan lasan ayafi ki won le maa sin Mi \\ Emi ko fe ese (ina ilo) kan lowo won ati pe Emi ko si fe ki won fun Mi ni ounje \\ Dajudaju Olohun ni Olupese Alagbara ti o le.'' Q 51:56-58.

Deedee iru awon ojuse ti n be lorun omoniyan gele naa ni n be ni orun awon naa, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِذْ صَرَفْنَا إِلَيْكَ نَفَرًا مِنَ الْجِنِّ يَسْتَمِعُونَ الْقُرْآنَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوا أَنْصِتُوا فَلَمَّا قُضِيَ وَلَّوْا إِلَى قَوْمِهِمْ مُنْذِرِينَ (29) قَالُوا يَا قَوْمَنَا إِنَّا سَمِعْنَا كِتَابًا أُنْزِلَ مِنْ بَعْدِ مُوسَى مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ يَهْدِي إِلَى الْحَقِّ وَإِلَى طَرِيقٍ مُسْتَقِيمٍ (30)

''Ati pe (ki o se iranti) nigbati A seri awon ijo kan ninu awon alijannu si o, ti won ngbo Al Kurani; nigbati won pe sibe, won so pe: E dake, nigbti A pari re, won yi pada lo si odo awon eniyan won, ni oluse ikilo (fun won) \\ Won so pe: Eyin eniyan wa dajudaju awa gbo akosile ti Won sokale leyin Musa ti o njeri ododo fun oun ti o ti wa siwaju re, o nfini mona sibi otito ati si oju ona ti o to.'' Q 46:29-30.

Olohun da won lati ara ina, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

خَلَقَ الْإِنْسَانَ مِنْ صَلْصَالٍ كَالْفَخَّارِ (14) وَخَلَقَ الْجَانَّ مِنْ مَارِجٍ مِنْ نَارٍ (15)

''(Oluwa) da eniyan lati ara amo gbigbe ti o da gegebi ikoko ti a fi ere ti a sun mo \\ O si da alijannu latara ahon ina.'' Q 55:14-15.

Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ (26) وَالْجَانَّ خَلَقْنَاهُ مِنْ قَبْلُ مِنْ نَارِ السَّمُومِ (27)

''Ati pe dajudaju Awa da eniyan lati ara amo dudu ti a sun jinna (ti a si yi pada si eda) \\ Ati pe alijannu A fi ina ti o gbona da a siwaju.'' Q 15:26-27.

 

ISEDA ADAMO

Adamo je baba gbogbo abara patapata oun naa si ni ipile won, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي جَاعِلٌ فِي الْأَرْضِ خَلِيفَةً قَالُوا أَتَجْعَلُ فِيهَا مَنْ يُفْسِدُ فِيهَا وَيَسْفِكُ الدِّمَاءَ وَنَحْنُ نُسَبِّحُ بِحَمْدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَ قَالَ إِنِّي أَعْلَمُ مَا لَا تَعْلَمُونَ(30) وَعَلَّمَ آدَمَ الْأَسْمَاءَ كُلَّهَا ثُمَّ عَرَضَهُمْ عَلَى الْمَلَائِكَةِ فَقَالَ أَنبِئُونِي بِأَسْمَاءِ هَؤُلَاءِ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(31) قَالُوا سُبْحَانَكَ لَا عِلْمَ لَنَا إِلَّا مَا عَلَّمْتَنَا إِنَّكَ أَنتَ الْعَلِيمُ الْحَكِيمُ(32) قَالَ يَا آدَمُ أَنبِئْهُم بِأَسْمَائِهِمْ فَلَمَّا أَنبَأَهُم بِأَسْمَائِهِمْ قَالَ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ إِنِّي أَعْلَمُ غَيْبَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَأَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا كُنتُمْ تَكْتُمُونَ(33) وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَى وَاسْتَكْبَرَ وَكَانَ مِنَ الْكَافِرِينَ(34) وَقُلْنَا يَا آدَمُ اسْكُنْ أَنتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ وَكُلَا مِنْهَا رَغَدًا حَيْثُ شِئْتُمَا وَلَا تَقْرَبَا هَذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الظَّالِمِينَ(35) فَأَزَلَّهُمَا الشَّيْطَانُ عَنْهَا فَأَخْرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِ وَقُلْنَا اهْبِطُوا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ وَلَكُمْ فِي الْأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَى حِينٍ(36) فَتَلَقَّى آدَمُ مِن رَّبِّهِ كَلِمَاتٍ فَتَابَ عَلَيْهِ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيم(37) قُلْنَا اهْبِطُوا مِنْهَا جَمِيعًا فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدًى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(38) وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(39)

''Nigbati Oluwa re s iwi fun awon Malaika pe: Emi yoo fi arole kan si ori ile, won wi pe: Ire yoo ha fi si ori ile eni ti yoo maa se ibaje lori re, ti won yoo si maa ta eje sile; awa si n se afomo iyin Re, a sin fi ogo fun O? O si wi pe: Emi mo oun ti eyin ko mo \\ '' O si oruko gbogbo nkan mo Adamo, leyinna O gbe won siwaju awon Malaika, O si wipe: e so orukan awon nkan wonyi fun Mi ti eyin baje olotito \\ Won wipe: O ogo ni fun O, kosi imo kan fun wa ayafi eyiti O fi mo wa, dajudaju Ire ni Olumo-Ologbon \\ O wipe: Adamo, so oruko won fun won, nigbati o so oruko won fun won, Olohun wipe: Nje Emi ko wa ti so fun yin pe dajudaju Emi mo ohun ti o pamo ni orun ati aye, Mo si tun mo ohun ti e fihan ati eyiti e fi pamo \\ Nigbati A wa si wi fun awon Malaika pe; E teriba fun Adamo, won si teriba ayafi Iblisu nikan bi o ko, o si se igberaga o si je okan ninu awon alaigbagbo \\ Awa wipe: Adamo! Iwo ati iyawo re, e ma gbe inu ogba-idera na, ki e si ma je ninu re nigbefe ni aye kaye ti e ba fe, sugbon e mase sunmo igi yi ki e ma ba di ara awon alabosi \\ Sugbon esu mu awon mejeji ye ese kuro ninu re, o si mu won jade kuro ninu aye ti awon mejeji ti wa, Awa si wipe: E sokale, ki apakan yin ma ba apakan se ota o si nbe fun lori ile ibugbe kan ati ese fun igba die\\ Leyinna Adamo ri awon oro kan gba lati odo Oluwa re, nitorina O gba ironupiwada re, dajudaju On ni Olugba-ironupiwada Alanu \\ Awa wipe: E sokale kuro ninu re patapata, nitorina dajudaju itosona yoo ma de wa ba yin lati odo Mi; nigbana, enikeni ti o ba tele itosona Mi, iberu ki yoo si fun won, won ki yoo si banuje \\ Atipe awon ti won saigbagbo ti won si pe awon Ayah wa ni iro, gbogbo awon wonyi ni ero na, won yoo si se gbere ninu re". Q 2:30-39.

Lati ara re ni awon ominyan ti pile, nitori naa odo re naa ni wo fori so ti won yoo si maa se afiti ara won si ni ibamu si oun ti Olohun Onibukun ti ola Re ga so wi pe:

يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ

''Mo pe eyin eniyan: e beru Oluwa yin, Eni ti o se eda yin latara emi kan soso.'' Q 4:1.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) naa tun salaye nipa paapaa oro naa bayi pe:

"يا أيها الناس إن ربكم واحد، وإن أباكم واحد، كلكم لآدم وآدم من تراب، إن أكرمكم عند الله أتقاكم، ليس لعربي فضل على أعجمي ولا لعجمي على عربي ولا أحمر على أبيض ولا أبيض على أحمر إلا بالتقوى

''Mo pe eyin eniyan: dajudaju okansoso ni Oluwa yin, ati pe dajudaju okan naa ni baba gbogbo yin, gbogbo yin patapata ni e se lati ara Adamo, won si da Adamo latara yerupe. Dajudaju eni ti o je alaponle ju lo ninu yin ni odo Olohun ni eni ti o paya (Olohun) ju lo. Ko si aju lo kannkan fun larubawa lori eni ti kii se larubawa bakan naa ko si aju lo fun eni ti kii se larubawa lori larubawa, bakan naa ni ko si aju lo fun alawo pupa lori alawo funfun, beeni ko si fun alawo funfun lori alawo pupa ayafi ni abala iberu Olohun.'' (Ahmad).

 

Bawo Ni Ideda Adamo Se Ri ?

Olohun ti mimo n be fun ti ola Re ga salaye wi pe Oun da Adamo latara yerupe yala o pe ni ile ni, gegebi O se so ninu oro Re pe:

إِنَّ مَثَلَ عِيسَى عِنْدَ اللَّهِ كَمَثَلِ آدَمَ خَلَقَهُ مِنْ تُرَابٍ ثُمَّ قَالَ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ (59)

''Dajudaju Isa ni odo Olohun o da bi apejuwe Adamo; O se eda re lati ara yerupe, leyin naa o s iwi fun un pe: je bee, o si je bee.'' Q 3:59.

Tabi O pe ni ere, eyi ti o pin si orisirisi ni ibamu si lile re, eleyi ni Olohun so ninu ese oro yip e:

هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ طِينٍ ثُمَّ قَضَى أَجَلًا وَأَجَلٌ مُسَمًّى عِنْدَهُ ثُمَّ أَنْتُمْ تَمْتَرُونَ (2)

''Oun naa ni Eni ti O da ere, leyin naa O fi igba si i. ati igba kan ti O fun ni oruko n be lodo Re, sibesibe e tun siyemeji.'' Q 6:2.

Tabi O pe ni amo ti o le mo ara won, Olohun ti ola Re ga so pe:

فَاسْتَفْتِهِمْ أَهُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمْ مَنْ خَلَقْنَا إِنَّا خَلَقْنَاهُمْ مِنْ طِينٍ لَازِبٍ (11)

''Bi won leere bi awon ni won le ju lati da ni tabi awon ti A da. Dajudaju Awa ni A da won (babanla won Adamo) lati inu amo ti o le (mo ara won).'' Q 37:11.

Tabi O kan so nipa awon ipele ti o gba koja gegebi amo gbigbe tabi ere ti a sun jona, gegebi oro Olohun ti ola Re ga ti O so bayi pe:

خَلَقَ الْإِنْسَانَ مِنْ صَلْصَالٍ كَالْفَخَّارِ (14)

''(Oluwa) da eniyan lati ara amo gbigbe ti o da gegebi ikoko ti a fi ere ti a sun mo.'' Q 55:14.

Tabi O pe ni amo dudu ti a sun jina, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ (26)

''Ati pe dajudaju Awa ni A da eniyan lati ara amo dudu ti a sun jina ti A si yi pada si eda.'' Q 15:26.

Gbogbo awon orisirisi oruko wonyi latara nnkankan naa ni won ti wa. Nitori naa Olohun ti mimo n be fun se eda Adamo latara erofo ti o gba orisirisi ipele koja, leyin naa Olohun fi sile fun igba die, leyin naa O fe emi si lara lati odo Re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ (28) فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِنْ رُوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ (29) فَسَجَدَ الْمَلَائِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ (30) إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَى أَنْ يَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ (31)

''Ati pe (ki o ranti) igbati Oluwa re wi fun awon Malaika Pe: Emi fe da abara kan lati inu amo dudu ti o jinna ti a yi pada (si eda) \\ Nigba ti Mo se e dogba tan Mo si fe ninu emi Mi sinu re, nigba naa (Mo wi pe): E te lo sile ni eni ti o maa teriba (fun un) \\ Nitori naa gbogbo awon Malaika patapata si teriba \\ Ayafi Ibilisu (esu) o ko lati wa ninu awon ti o teriba.'' Q 15:28-31.

Leyin naa O se imaa bisi ati imaa resi omoniyan latara omi logbologbo ti njade lati ibi eegun eyin won, eyi tii se ato. Olohun ti ola Re ga soro lori eleyi ninu ese wura yi pe:

الَّذِي أَحْسَنَ كُلَّ شَيْءٍ خَلَقَهُ وَبَدَأَ خَلْقَ الْإِنْسَانِ مِنْ طِينٍ (7) ثُمَّ جَعَلَ نَسْلَهُ مِنْ سُلَالَةٍ مِنْ مَاءٍ مَهِينٍ (8) ثُمَّ سَوَّاهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِنْ رُوحِهِ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ قَلِيلًا مَا تَشْكُرُونَ (9)

''Eni ti O se gbogbo nnkan ti O da eda Re daradara ti O si bere eda eniyan lati ibi amo \\ Leyin naa O se awon aromodomo re lati ara omi logbologbo ti o je omi ti o le \\ Leyin naa O se e ni dogbadogba, O si fe ninu emi Re si i. O si se igboro fun yin ati awon iriran ati awon okan, die ni ope yin ti e nda.'' Q 32: 7-9.

Gegebi o se jepe yerupe ni ipile omoniyan ti o si jepe inu re ni o ti wa, bakan naa si ni pe ibe ni won yoo pada si, inu re naa ni won yoo ti dide ni ojo igbende

مِنْهَا خَلَقْنَاكُمْ وَفِيهَا نُعِيدُكُمْ وَمِنْهَا نُخْرِجُكُمْ تَارَةً أُخْرَى (55)

''Ninu re ni A ti da yin ati pe ninu re ni A o da yin pada si ati pe lati inu re ni A o ti fa yin yo ni igba miiran.'' Q 20:55.

 

Iroyin Adamo (ike ati ola Olohun ki o ma ba a):

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) se iro Adamo (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) bayi pe: 

خلق الله آدم وطوله ستون ذراعا ثم قال: اذهب فسلم على أولئك من الملائكة فاستمع ما يحيونك تحيتك وتحية ذريتك فقال: السلام عليكم فقالوا: السلام عليك ورحمة الله فزادوه ورحمة الله فكل من يدخل الجنة على صورة آدم فلم يزل الخلق ينقص حتى الآن"

''Olohun da Adamo ti o si ga ni odiwon ogota igunpa, leyin naa ni O so pe: Lo salamo si awon Malaika ti o wa lookan nni, ki o si teti si bi won yoo se ki o (eleyi nni) ni yoo je kiki fun iwo ati awon aromodomo re, ni o ba so pe: Alafia Olohun ki o maa ba yin (As salam alaykum, won si dahun wi pe: Alaafia Olohun ki o ma ba o ati ike Re, won se alekun '' ati ike Re '' , gbogbo enikeni ti o ba wo ogba idera ni yoo wa lori aworan Adamo (ni giga) bio tileje pe awon eniyan ko yee maa dinku (ni giga) titi di asiko yi.'' (Al Bukhari).

 

Okunfa Ipin Si Orisirisi Awon Omo Adamo

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) salaye idi ti awon aromodomo Adamo fi je oniranran ni awo, irisi ati ni adamo won. O so ninu oro re bayi pe:

ان الله تعالى خلق آدم من قبضة قبضها من جميع الأرض فجاء بنو آدم على قدر الأرض منهم الأحمر والأسود والأبيض والأصفر وبين ذلك والسهل والحزن والخبيث والطيب

''Dajudaju Olohun se eda Adamo lati ara ekunwo yerupe kan ti O bu latara orisirisi ipin ti ile pin si, nitori idi eyi ni awon omo Adamo se wa ni ibamu si awon ile naa, o n be ninu won eni ti o pupa, o si n be ninu won eni ti o dudu, o tin wa ninu won eni ti o funfun o si n be ninu won eni ti o pupa resuresu, o si tun wa ninu won eni ti o wa laarin meji, o n be ni u won eni ti adamo re ro (pelepele) ati eni ti adamo re le, o n be ninu won eni ti iwa re dara, o si n be ninu won eni ti iwa buru.'' (Ibn Hibban) 

 

ISEDA HAWAU IYA GBOGBO EDA ABARA (OMONIYAN)

Leyin ti Olohun pari iseda Adamo (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) tan, O seda iyawo re Hawau lati ara efanha re ti egbe osi, ki o le maa fokanbale sodo re ati ki awon eniyan le fonka si ori ile latara awon mejeeji. Olohun tiola Re so bayi pe:

يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَاءً وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي تَسَاءَلُونَ بِهِ وَالْأَرْحَامَ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا (1)

''Mo pee yin eniyan: E beru Oluwa yin, Eni ti O se eda yin lati ara emi kansoso O si se eda aya re lati ara re, O si tan opolopo okunrin ati obinrin kale lati ara awon mejeeji, ki e si beru Olohun, Eni ti e fi n be ara yin ati okun ibi, dajudaju Olohun je Oluso lori yin.'' Q 4:1.

Bakan naa ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun so pe:

من كان يؤمن بالله واليوم الآخر فلا يؤذي جاره واستوصوا بالنساء خيرا فإنهن خلقن من ضلع وإن أعوج شيء في الضلع أعلاه فإن ذهبت تقيمه كسرته وإن تركته لم يزل أعوج فاستوصوا بالنساء خيرا"

''Enikeni ti o ba ni igbagbo ninu Olohun ati ojo ikeyin, ko gbodo fi ara ni alabagbe re. E so asotele daadaa nipa awon obinrin, nitori pe lati ara efonha ni Won ti da won, l'eyi tio si jepe dajudaju eyi ti o gun (te) ju lo ninu efonha naa ni eyi ti o wa ni oke, ti o ba wa so pe o fee naa (gbooro) kikan ni yoo kan an, ti o ba si fi sile ko ni kuro ni tite (wiwo) kokoro, nitori naa e so asotele daradara nipa awon obinrin.'' (Al Bukhari)

 

IBUGBE ADAMO (IKE ATI OLA OLOHUN KI O MA BA A) ATI HAWAU

Inu ogba idera (Al jannah) ni ibugbe awon mejeeji siwaju ki Olohun to le won kuro nibe lo si ori ile latara ese eyi ti Adamo (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) da, Olohun ti ola Re ga so pe:

وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَى (116) فَقُلْنَا يَا آدَمُ إِنَّ هَذَا عَدُوٌّ لَكَ وَلِزَوْجِكَ فَلَا يُخْرِجَنَّكُمَا مِنَ الْجَنَّةِ فَتَشْقَى (117) إِنَّ لَكَ أَلَّا تَجُوعَ فِيهَا وَلَا تَعْرَى (118) وَأَنَّكَ لَا تَظْمَأُ فِيهَا وَلَا تَضْحَى (119) فَوَسْوَسَ إِلَيْهِ الشَّيْطَانُ قَالَ يَا آدَمُ هَلْ أَدُلُّكَ عَلَى شَجَرَةِ الْخُلْدِ وَمُلْكٍ لَا يَبْلَى (120) فَأَكَلَا مِنْهَا فَبَدَتْ لَهُمَا سَوْآتُهُمَا وَطَفِقَا يَخْصِفَانِ عَلَيْهِمَا مِنْ وَرَقِ الْجَنَّةِ وَعَصَى آدَمُ رَبَّهُ فَغَوَى (121) ثُمَّ اجْتَبَاهُ رَبُّهُ فَتَابَ عَلَيْهِ وَهَدَى (122) قَالَ اهْبِطَا مِنْهَا جَمِيعًا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ مِنِّي هُدًى فَمَنِ اتَّبَعَ هُدَايَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشْقَى (123) وَمَنْ أَعْرَضَ عَنْ ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنْكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَى (124)

''Ati pe nigba ti A so fun awon Malaika pe e forikanle fun Adamo, won forikanle afi ibilisi ni o ko \\ Nitori naa Awa so pe: Ire Adamo, dajudaju eleyi bay iota ni o je si iwo ati aya re; nitori naa maa se je ki o yo eyin mejeeji jade ninu ogba idera yi ki o ma baa se oriburuku \\ Dajudaju ebi ko ni pa o beeni o ko ni wa ni ihoho ninu re \\ Ati pe ongbe ko ni gbe o beeni oorun ko ni pa o ninu re \\ Sugbon esu ko erokero si i lokan; o wi pe: Ire Adamo, se ki emi fi igi (ti yoo mu o wa) gbere han o ati ijoba ti ko ni lopin \\ Nitori naa awon mejeeji si je ninu re, nigba naa ihoho aon mejeeji si han si won, awon mejeeji bere si le ninu ewe ogba naa mo ara won. Adamo si se aigboran si Oluwa re o si koja aala \\ Leyin naa ni Oluwa re sa a lesa, O si gba ironupiwada re O si to o sona \\ O wi pe: Eyin mejeeji, e jade ninu re patapata, ki apakan yin maa je ota fun apakan. Nigbati itosona ba wa ba yin lati odo Mi; eni ti o ba si tele ona Mi naa, (oluware) ko ni sina beeni koni se oriburuku \\ Eni ti o ba seri kuro nibi iranti Mi dajudaju igbesi aye re inira ni yoo wa fun un, A o si gbe dide ni ojo ajinde ni afoju.'' Q 20:116-124.

 

 

 

IBERE RIRAN AWON OJISE (IKE ATI OLA OLOHUN KI O MA BA WON) SI AWON ENIYAN

Leyin egberun odun ti Adamo (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) papoda, iyapa sele lori ile, bayi ni Olohun si bere si ni ran awon Ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) si awon omoniyan. Ibn Abas (Olohun ki o yonu si) so pe: ''alafo ti o wa laarin Adamo ati Nuha (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) je egberun odun, gbogbo awon ti o semi ni asiko naa si wa lori esin Olohun tii se ododo, leyin naa ni won se iyapa enu ti Olohun si (bere si) gbe awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) dide ki won le je olufunni niro idunnu (fun awon oluse ti Olohun) ati olukilo (fun awon ti won ba ko ti Olohun).'' (Al Mustadrak).

Eni ti o je akoko ninu awon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) leyin iyapa enu awon eniyan ni Nuha (ike ati ola Olohun ki o ma ba a), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:  

إِنَّا أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ كَمَا أَوْحَيْنَا إِلَى نُوحٍ وَالنَّبِيِّينَ مِنْ بَعْدِهِ

''Dajudaju A ran se si o gegebi A se ran se si Nuha ati awon Annabi leyin re.'' Q 4:163.

Ni paapaa, Olohun ti daruko awon kan ninu awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba) yi, Olohun ti ola Re ga so ninu oro Re bayi pe:

وَتِلْكَ حُجَّتُنَا آتَيْنَاهَا إِبْرَاهِيمَ عَلَى قَوْمِهِ نَرْفَعُ دَرَجَاتٍ مَنْ نَشَاءُ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٌ (83) وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ كُلًّا هَدَيْنَا وَنُوحًا هَدَيْنَا مِنْ قَبْلُ وَمِنْ ذُرِّيَّتِهِ دَاوُودَ وَسُلَيْمَانَ وَأَيُّوبَ وَيُوسُفَ وَمُوسَى وَهَارُونَ وَكَذَلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ (84) وَزَكَرِيَّا وَيَحْيَى وَعِيسَى وَإِلْيَاسَ كُلٌّ مِنَ الصَّالِحِينَ (85) وَإِسْمَاعِيلَ وَالْيَسَعَ وَيُونُسَ وَلُوطًا وَكُلًّا فَضَّلْنَا عَلَى الْعَالَمِينَ (86) وَمِنْ آبَائِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ وَإِخْوَانِهِمْ وَاجْتَبَيْنَاهُمْ وَهَدَيْنَاهُمْ إِلَى صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ (87)

''Eyi ni idi oro wa ti A fifun Ibrahima lori awon eniyan re. A n gbe eni ti o ba hu wa ga ni ti iyi. Dajudaju Oluwa re je Ologbon Oni mimo \\ Awa si fun un niIsihaka ati Yakuba, Awa si to okookan won si ona; Awa si to Nuha si ona siwaju ati ninu awon aromodomo re, Dauda ati Sulaiman ati Ayuba ati Yusufu ati Musa ati Haruna. Bayi ni A se nsan esan fun awon oniwa rere \\ Ati Zakariya ati Yahya ati Isa ati Iliyasa: gbogbo won lo n be ninu awon enirere \\ Ati Ismaila ati Alyasaati Yunusa ati Lutu; gbogbo (won) ni A se aju lo fun lori awon eda \\ Ati ninu awon baba won ati aromodomo won ati awon arakunrin won, Awa si sa won lesa, A si to won si ona kan ti o to'.' Q 6:83-87.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

قُولُوا آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنْزِلَ إِلَيْنَا وَمَا أُنْزِلَ إِلَى إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَمَا أُوتِيَ مُوسَى وَعِيسَى وَمَا أُوتِيَ النَّبِيُّونَ مِنْ رَبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْهُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ (136)

''E wi pe: Awa gba Olohun gbo, ati oun ti O soka le fun wa ati oun ti O soka le fun Ibrahima, Ismaila, Ishaka, Yakuba ati awon aromodomo; ati oun ti A fi fun Musa ati ti Isa ati oun ti A fi fun awon Anabi lati odo Olohun won, awa ko ya okan soto ninu won, awa si je Musulumi (eni ti o ju ara re sile fun Un).'' Q 2:136.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

وَإِسْمَاعِيلَ وَإِدْرِيسَ وَذَا الْكِفْلِ كُلٌّ مِنَ الصَّابِرِينَ (85)

''Ati Ismaila ati Idrisa ati Sulikifuli, okookan won n be ninu awon onisuuru.'' Q 21:85.

Leyi ti o si jepe o wa ninu awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) wonyi ti Olohun ko soro nipa won rara ninu Al Kurani, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَرُسُلًا قَدْ قَصَصْنَاهُمْ عَلَيْكَ مِنْ قَبْلُ وَرُسُلًا لَمْ نَقْصُصْهُمْ عَلَيْكَ وَكَلَّمَ اللَّهُ مُوسَى تَكْلِيمًا (164)

''Awon ojise kan n be ti A daruko won fun o siwaju, awon ojise kan si n be ti A ko daruko won fun o. Ati pe Olohun ba Musa soro ni oro gan an.'' Q 4:164.

Olohun ti mimo n be fun ma nran awon Ojise ati awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) lati igba de igba ti won si maa nda awon eniyan pada sibi imo Olohun won ni okan soso ati pe ki maa se ijosin fun Oun nikan soso. Gbogbo won patapata, bere latiro Alakooko ninu won titi o fi de ori eni ti o gbeyin, ni ipepe won je nnkankan naa lori imo Olohun ni okan soso, eleyi ti o tumo si mimu Olohun ni okan soso ninu adisokan, oro siso ati ise sise, pelu sise aigbagbo si gbogbo oun ti awon eniyan njosin fun leyin Olohun Oba Okansoso. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَسُولًا أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاجْتَنِبُوا الطَّاغُوتَ فَمِنْهُمْ مَنْ هَدَى اللَّهُ وَمِنْهُمْ مَنْ حَقَّتْ عَلَيْهِ الضَّلَالَةُ فَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ (36)

''Ati pe dajudaju ati gbe ojise kookan dide ninu ijo kookan (pe): Ki e sin Olohun ki e si jina si awon orisa. Eni ti Olohun fi mona n be ninu won ati pe eni ti isina tosi n be ninu won. Nitori naa e maa rin l'ori ile leyin naa ki e maa woye si bi atubotan awon opuro ti ri.'' Q 16:36.

Sugbon awon ilana ofin ati awon ojuse oranyan ti ijo kookan fin se ijosin ni o yato si ara won, o n be ninu won eni ti won se awon nnkankan ni oranyan fun sugbon ti won ko si se ni oranyan fun awon miiran, eleyi je idanwo lati odo Olohun. olohun ti ola Re ga so bayi pe:

لِكُلٍّ جَعَلْنَا مِنْكُمْ شِرْعَةً وَمِنْهَاجًا وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَجَعَلَكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَلَكِنْ لِيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ فَاسْتَبِقُوا الْخَيْرَاتِ

''Onikaluku yin ni A ti se ofin ati ilana esin fun. Ti o ba sepe Olohun fe ni dajudaju ko ba se yin ni ijo kansoso. Sugbon ki O le dayin wo nipa oun ti O fun yin.'' Q 5:48.

Bayi ni o ri titi ti Olohun fi fi opin si ilana ije ojise pelu Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba a), eni ti O ran gbogbo eda patapata. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

مَا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَا أَحَدٍ مِنْ رِجَالِكُمْ وَلَكِنْ رَسُولَ اللَّهِ وَخَاتَمَ النَّبِيِّينَ

''Muhammad ki i se baba fun enikannkan ninu awon arakunrin yin, sugbon (o je) Ojise Olohun ati ipekun awon Anabi.'' Q 33:40.

Ninu awon oun ti awon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) n pepe si naa ni; ini igbagbo ninu bibe Olohun, Oba Aso, Okansoso, Adeda, Olupebubu, imaa josin fun Oun nikan ati mimaa fi gbogbo alamori ti si odo Re nikan. Eleyin je okan pataki ninu oun ti o ma n se okunfa oriire fun omoniyan ninu emi ati ifokanbale ati ini alaafia lakaye. Eleyi si ni oun ti Olohun ti ola Re ga salaye fun ojise Re pelu oro Re ti O so bayi pe: 

وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ (107)"

''Ati pe Awa ko wule ran o nise bikosepe ki o le je ike fun gbogbo agbaye.'' Q 21:107.

Eri tabi itoka lori pe eni ti o ba ni igbagbo ododo si Olohun ati awon oun ti o wa lati odo Re yoo se oriire (ifokanbale) lailai, ni awon oun ti a ri gbangba gbangba ti o n sele si awon awujo ti ntako bibe Olohun ti ola Re ga, ti won si tun ntako awon ilana ofin Re, ninu aigbaye gbadun ti n be fun won ati idaamu daabo emi pelu ifunpinpin, eleyi ti o se okunfa ki won maa lo awon oogun oloro ni orisirisi lati fi pa ironu re ati lati gbe ifunpinpin emi ti n be fun won fuse, koda o n be ninu won ti o maa npari oro re si ibi ki o moomo se iku pa ara re yala pelu ki o pokun so tabi ki o pa ara re ni ona miiran- Olohun ki O sowa nibe-.

Eyi ti o daju saka ni pe awon nnkan wonyi ki i se ohun ti a n pe ni oriire (ifokanbale), ti o ba si jepe oriire n be nibe ajepe iru oriire je eyi ti o ni adinku ti o si wa fun igba kekere, apejuwe iru oriire bayi si ni apejuwe eni ti o mu omi iyo eyi ti ko le re l'ongbe bikosepe yoo tun se alekun ongbe kun ongbe re ni. Sugbon ki omoniyan ni igbagbo ododo ninu bibe Olohun ti ola Re ga, ki o si ro ara re sile fun Un pelu ki o juwo juse sile fun Un, ki o si yepere ara re niwaju Re, ki o si maa tele awon ofin ati ilana Re, eyi ti o si jepe Oun (Olohun) ni yoo dajo paapaa oriire ati ifokanbale emi ati ara lori gbogbo alamori patapata.

 

 

 

TANI OMONIYAN ?

Oun naa ni eda kan ti Olohun da ni eya ti o dara ju lo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

لَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ فِي أَحْسَنِ تَقْوِيمٍ (4)

'' Dajudaju A da eniyan ni eya ti o dara ju lo.'' Q 95:4.

Leyin naa O se ni asepe O si se awon orike re dogba ni eni ti O gbe duro daradara, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَا أَيُّهَا الْإِنْسَانُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ الْكَرِيمِ (6) الَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّاكَ فَعَدَلَكَ (7) فِي أَيِّ صُورَةٍ مَا شَاءَ رَكَّبَكَ (8)

''Ire eniyan ki lo tan o je si Oluwa re Alabukun \\ Eni ti O da o ti O si se o ni asepe, leyin naa O se awon orike re dogba (O si tun gbe e duro daradara).'' Q 82:6-8.

O gbe e kale ni aworan ti o dara ti o si pe ju lo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ قَرَارًا وَالسَّمَاءَ بِنَاءً وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَرَزَقَكُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ ذَلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ فَتَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ (64)

''Olohun ni Eni ti O se ile fun yin ni petepere ti O si se sanmo ni oun ti a mo (leyin lori), ti O si ya aworan yin O si se aworan yin naa daradara, O si se arisiki fun yin ni eyi ti o mo. (Eni ti O se eyi fun yin) ni Olohun Oluwa yin, nitori naa ibunkun ni fun Olohun Oluwa gbogbo eda.'' Q 40:64.

Olohun gbe ola fun un O se aponle fun un lori gbogbo eda patapata. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلًا (70)

''Ati pe dajudaju Awa se aponle fun awon omo (Anabi) Adamo, Awa gbe won (rin) lori ile ati odo, Awa si nfun won ni ije imu ninu awon oun ti o dara, Awa si da won lola ju opolopo ninu awon eda ti A da niti ola.” Q 17:70.

Bakan naa ni o pe o ro gbogbo oun ti n be ni aye fun un. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَسَخَّرَ لَكُمْ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مِنْهُ..."

''Ati pe O te lori ba fun yin oun ti o wa ni sanmo ati oun ti o wa ni ile patapata, lati odo ara Re.'' Q 45:13.

Nitori idi eyi, omoniyan je eda kan ti o da duro ni paapaa re, ti ko wa lati ara eda miiran ninu awon eda. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

الَّذِي أَحْسَنَ كُلَّ شَيْءٍ خَلَقَهُ وَبَدَأَ خَلْقَ الْإِنْسَانِ مِنْ طِينٍ (7)

''Eni ti O se gbogbo nnkan ti O da eda Re daradara ti O si bere eda omoniyan lati ibi amo.'' Q 32:7.

Nje se won wa j'ora won bi, awon oro olowo iyebiye wonyi ti ntoka lori titobi ati ipo ti o ga ti omoniyan wa ninu esin Islam pelu awon iwoyesi lasan (ti awon ti ko gbagbo ninu bibe Olohun gbe kale) eyi ti o fi omoniyan si ipo eranko? Eleyi ti Al Kurani ko fi royin omoniyan rara ayafi nigba ti o teri gungun sinu ifekufe emi eyi ti ko ni aala, tabi nigba ti ko ba lo awon idera ti Olohun se fun un, yala idera lakaye ni tabi igboro, tabi iriran lati se ironu nipa ijoba sanmo ati ile. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَقَدْ ذَرَأْنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرًا مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ لَهُمْ قُلُوبٌ لَا يَفْقَهُونَ بِهَا وَلَهُمْ أَعْيُنٌ لَا يُبْصِرُونَ بِهَا وَلَهُمْ آذَانٌ لَا يَسْمَعُونَ بِهَا أُولَئِكَ كَالْأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ أُولَئِكَ هُمُ الْغَافِلُونَ (179)

''Dajudaju A da opolopo eniyan ati alijonnu fun ina Jahanama (nitori pe) okan n be fun won, won ko fi ronu, oju si n be fun won, won ko fi riran, eti si n be fun won, won ko fi gboro. Awon elewonyi da bi eran; e fi eleyini sile, won sina (ju eran lo) awon elewonyi ni won ko kula (nipa oro Oluwa).'' Q 7:179.

Nitori pe ona ti o dara ju lo lati maa lo awon eya ara wonyi, oun naa ni mimaa fi won se ironu, iru eyiti o maa n se okunfa ki awon onilakaye eniyan mona lo sibi ododo ati dida Olohun mo pelu nini igbagbo ododo ninu Re, biotile jepe gbogbo eleyi maa n sele latara ifini se konge lati odo Olohun ti ola Re ga.

Ibn Al qayyim (ki ike Olohun maa be fun un) so pe: ''loo mo pe, dajudaju Olohun ti ola Re ga sa omoniyan lesa laarin awon eda Re pelu pe O se aponle fun un O si gbe ola fun un O si buyi kun un bakan naa, O da omoniyan nitori ara Re (lati maa se ijosin fun Oun nikansoso) O si da awon eda yoku nitori re (omoniyan). O sa a lesa fun dida Oun mo ati fun ife Re, O se ni alasunmo Re leyi ti ko se bee fun awon eda miiran. O ro gbogbo oun ti n be ni awon sanmo ati ile fun un pelu awon on ti n be laarin awon mejeeji, koda tofi dori awon Malaika awon ti won je alasunmo Re ju lo. O nlo won (awon Malaika) ni iran se fun awon omoniyan, O si se won ni oluso fun un yala nigbati o ba nsun tabi nigbati o ba ji, nigbati o ba n se irinajo tabi nigbati o ba wa ni ilu re. O so awon Tira Re kale fun un, O ran awon Ojise si, O doju oro ko o, O si ba a soro lati odo Re, O se awon kan ninu won ni aayo, alabasoro, ore tinutinu, esa ati awon onimimo, O se awon wonyi ni aaye ikoko (awon ti O maa nfi ikoko han nigba ti O ba wu U) ati ogbon (ti O maa nfi mo won) Re ati aaye ife Re. O se eda ogba idera (Al jannah) ati ina nitori won (omoniyan). Nitori naa ideda, ipani lase, isanni lesan ati ijeni niya wa fun eya omoniyan, nitori pe oun naa ni esa ninu awon eda, oun naa si ni eni ti ipani lase ati iko funni wa fun leyi ti esan rere tabi iya si n be fun un (ni ibamu si oun ti o ba se).'' (Madaariju As salikeen)

 

AWON IPELE IDEDA OMONIYAN

Omoniyan ko je nnkankan ni ipile re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

هَلْ أَتَى عَلَى الْإِنْسَانِ حِينٌ مِنَ الدَّهْرِ لَمْ يَكُنْ شَيْئًا مَذْكُورًا (1)

''Dajudaju igba kan ninu awon akoko ti rekoja lori omoniyan ti ko je kinikan ti a le daruko.'' Q 76:1.

Leyin igba naa ni won bere kikojo ideda re lati ibi omi ti o le ti o si nrun, Olohun ti ola Re ga so nipa eleyi pe:

أَلَمْ نَخْلُقْكُمْ مِنْ مَاءٍ مَهِينٍ (20) فَجَعَلْنَاهُ فِي قَرَارٍ مَكِينٍ (21) إِلَى قَدَرٍ مَعْلُومٍ (22) فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ الْقَادِرُونَ (23)"

''Nje A ko ti da yin lati inu omi ti ko lagbara (ole) \\ Leyin naa Awa fi i sinu aaye kan ti nnkankan ko le gun un \\ Titi lo di akoko kan ti A ti mo \\ A wa pa ebubu re, Awa ni A dara ju lo ninu awon olupebubu.'' Q 77:20-23.

Imam Al Gazali so bayi pe: ''Ki omoniyan woye si idera Olohun eyi ti O se fun; bi O se mu lati ipo iyepere, alaini ati ipo egbin bo si ipo aponle ti o ga, ti o wa di eni ti n be leyin igbati o ti je alaisi tele, ti o di alaaye leyin ti o ti wa ni ipo oku tele, ti o di eni ti nsoro leyin ti o ti je oyaya tele, ti o di eni ti o riran leyin ti o ti wa ni ipo afoju tele, ti o di alagbara leyin ti o ti o ti wa ni ipo ole tele, ti o di eni ti o mona leyin ti o ti wa ninu isina tele, ti o di eni ti o ni ikapa leyin ti o ti wa ni ipo ikagara tele, ti o di oloro leyin ti o ti wa ni ipo alaini. Ko je nnkankan ni paapaa re; nje nnkankan wa n be ti o yepere ju aije nnkankan lo bi? Nje nnkankan wa n be ti o kere ju aisi lo bi? Leyin naa ni o wa je nnkan latara fife ati ola Olohun lori re.'' (Ihya Ulumu deen)

 

LATARA KI NI WON TI DA OMONIYAN ?

 Olohun ti mimo n be fun ti ola Re si ga salaye wi pe ideda omoniyan ko waye bikosepe latara idapo laarin omi ti njade lati ara okunrin ati omi ti njade lati ara obinrin. Olohun ti ola Re ga so ninu oro Re bayi pe:

فَلْيَنْظُرِ الْإِنْسَانُ مِمَّ خُلِقَ (5) خُلِقَ مِنْ مَاءٍ دَافِقٍ (6) يَخْرُجُ مِنْ بَيْنِ الصُّلْبِ وَالتَّرَائِبِ (7)

''Nitori naa ki eniyan woye si oun ti A fi da a \\ A da a lati ibi omi ti ntu jade\\ O nyo jade lati aarin ibadi ati awon eegun aya.'' Q 86:5-7.

Bakan naa ni Olohun ti mimo n be fun tun salaye wi pe dajudaju omi yi ni o je okunfa imaa bisi ati pipo omoniyan lori ile. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ مِنَ الْمَاءِ بَشَرًا فَجَعَلَهُ نَسَبًا وَصِهْرًا وَكَانَ رَبُّكَ قَدِيرًا (54)

''Ati pe Oun ni Eni ti O da eniyan lati inu omi. Leyin naa O se e ni ibatan ati iran. Oluwa re je Alagbara.'' Q 25:54

Olohun ti ola Re ga tun salaye wi pe dajudaju eda tuntun yii yoo wa ni aaye kan ti o fokanbale ti ko si ni si ilapa aburu lori re titi di asiko ti Olohun ba fe ki o jade. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

أَلَمْ نَخْلُقْكُمْ مِنْ مَاءٍ مَهِينٍ (20) فَجَعَلْنَاهُ فِي قَرَارٍ مَكِينٍ (21) إِلَى قَدَرٍ مَعْلُومٍ (22) فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ الْقَادِرُونَ (23)

''Nje A ko ti dayin lati ibi omi ti ko l'agbara (ole) \\ Leyin naa A wa fi i sinu aaye kan ti nnkankan ko le gun un \\ Titi lo di akoko kan ti A ti mo \\ Awa pa ebubu re, Awa ni a dara ju lo ninu awon olupebubu.'' Q 77:20-23.

Bakan naa ni Olohun tun salaye wi pe dajudaju eda omoniyan yi yoo wa ninu okunkun meta, ti yoo maa ti ipele kan bo si ekeji titi yoo fi de ipele ti o pari pelu iyonda ati agbara Olohun, ti yio si jade si agbaye. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَخْلُقُكُمْ فِي بُطُونِ أُمَّه َاتِكُمْ خَلْقًا مِنْ بَعْدِ خَلْقٍ فِي ظُلُمَاتٍ ثَلَاثٍ

''O n se eda yin sinu awon ikun awon iya yin ni eda kan leyin dida kan sinu okunkun meta.'' Q 39:6.

 

AWON IPELE EYITI OMONIYAN RE KOJA (NI ASIKO IDEDA RE)

Ipele Alakooko: Omi logbologbo ti a ropo mo ara won, eyi ti o waye latara idapo omi (ato) okunrin ati eyi ti o waye latara obinrin. Olohun ti ola Re ga so pe:

وَأَنَّهُ خَلَقَ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنْثَى (45) مِنْ نُطْفَةٍ إِذَا تُمْنَى (46)

''Ati pe dajudaju Oun lo da eniyan ni orisi meji, okunrin ati obinrin \\ Lati ibi omi logbologbo nigbati won ba da (sinu apo omo).'' Q 53:45-46.

Ni ipele yi, ti o ba wu Olohun ti ola Re ga yoo pebubu ki awon omi okunrin ati ti obinrin naa parapo di okansoso, eleyi ni igbese ti ato fi ma parapo mo eyin ninu obinrin. Ti o ba si wu U yoo pebubu ki won ma parapo di okansoso, nigba yi ato ko ni parapo mo eyin ninu obinrin, bayi ni ato ati eyin naa yoo si di oku. Sugbon ti won ba parapo won yoo di omi logbologbo, eleyi si ni ipile ideda omoniyan. Olohun ti ola Re ga so pe:

إِنَّا خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ نُطْفَةٍ أَمْشَاجٍ نَبْتَلِيهِ فَجَعَلْنَاهُ سَمِيعًا بَصِيرًا (2)

''Dajudaju Awa ni A da omoniyan lati ara omi logbologbo ti aropo mo ara won, ki A le ba a dan an wo , nitori naa ni A se ni olugboro oluriran.'' Q 76:2.

Ati pe ni ipele yi, ti yoo wa ni omi logbologbo, gbogb iroyin omoniyan ni yoo pe si lara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُتِلَ الْإِنْسَانُ مَا أَكْفَرَهُ (17) مِنْ أَيِّ شَيْءٍ خَلَقَهُ (18) مِنْ نُطْفَةٍ خَلَقَهُ فَقَدَّرَهُ (19)

''Egun ni fun omoniyan, kini ohun ti o mu u se aimoore! \\ Kini (Olohun) fi da a? \\ Ninu omi logbologbo ni O ti da a. O si pebubu re.'' Q 80:17-19.

Ni asiko yi ni yio ti han (lati ara ipebubu Olohun) wi pe okunrin tabi obinrin, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

لِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ يَهَبُ لِمَنْ يَشَاءُ إِنَاثًا وَيَهَبُ لِمَنْ يَشَاءُ الذُّكُورَ (49) أَوْ يُزَوِّجُهُمْ ذُكْرَانًا وَإِنَاثًا وَيَجْعَلُ مَنْ يَشَاءُ عَقِيمًا إِنَّهُ عَلِيمٌ قَدِيرٌ (50)

''Ti Olohun ni ikapa sanmo ati ile. A maa da oun ti o ba fe (ni eda). A ta eni ti O ba fe lore omobinrin A si maa ta eni ti O ba fe lore omokunrin \\ Tabi ki O se won ni ako ati abo, A si maa se eni ti O ba fe ni agan. Dajudaju Oun ni Onimimo Alagbara.'' Q 42:49-50.

Olohun ti ola Re ga tun nso ninu oro Re bayi pe:

هُوَ الَّذِي يُصَوِّرُكُمْ فِي الأَرْحَامِ كَيْفَ يَشَاء لاَ إِلَـهَ إِلاَّ هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ

''Oun ni Eni ti O da yin sinu apoluke bi O se fe. Ko si Olohun miiran ayafi Oun, Alagbara, Ologbon.'' Q 3:6.

Ati pe omi logbologbo ti apopo ni ipele yi, ninu ki o wale lati inu apoluke ki o si jade sita re, ni ibamu si ipebubu ati agbara Olohun Oba Abiyi, Oba ti O gbongbon lori re wi pe ki o ma fesemule sinu apoluke. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

اللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَحْمِلُ كُلُّ أُنْثَى وَمَا تَغِيضُ الْأَرْحَامُ وَمَا تَزْدَادُ وَكُلُّ شَيْءٍ عِنْدَهُ بِمِقْدَارٍ (8)

''Olohun mo ohun ti onikaluku obinrin nru kiri (ni oyun) ati oun ti apo omo fi din (ojo) ku ati eyi ti o le (ojo) si. gbogbo nnkan ni o ni osunwon lodo Re.'' Q 13:8.

Ti o ba si wu Olohun Alaponle yoo pebubu ki o sopo mo apoluke, leyi ti yoo si fi bosi ipele eyi ti yoo fi di eje kiki. Bayi ni yoo si fidimule si ara ile omo ti yoo si maa ri ije imu re lati ara re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَنُقِرُّ فِي الْأَرْحَامِ مَا نَشَاءُ إِلَى أَجَلٍ مُسَمًّى ثُمَّ نُخْرِجُكُمْ طِفْلًا

''Ati pe A nfi oun ti A ba fe rinle sinu apo ibimo titi lo di asiko ti A so, leyin naa A o mu yin jade ni oponlo.'' Q 22:5.

Ipele Eleekeji: Eje Kiki, eleyi ri bee nitori pe ato naa ti sopo mo apo ibimo lati maa wa ije imu re lati ara eje, won se afijo re pelu idun tabi eegbon eyi ti o ma nfi eje awon eda ti o ba ti sopo mo se ounje. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

اقْرَأْ بِاسْمِ رَبِّكَ الَّذِي خَلَقَ (1) خَلَقَ الْإِنْسَانَ مِنْ عَلَقٍ (2)

''Ma aka pelu oruko Oluwa re ti O da eda \\ O fi eje didi da eniyan.'' Q 96:1-2.

Olohun ti ola Re ga tun so wi pe:

أَيَحْسَبُ الْإِنْسَانُ أَنْ يُتْرَكَ سُدًى (36) أَلَمْ يَكُ نُطْفَةً مِنْ مَنِيٍّ يُمْنَى (37) ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّى (38) فَجَعَلَ مِنْهُ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنْثَى (39)

''Se omoniyan wa ro ni pe A o fi oun sile lasan \\ Abi oun ko ti je omi logbologbo ti o jade? \\ Leyin naaa ni o di eje didi O si da a ni adape \\ O mu jade ninu re tokotaya ni takotabo.'' Q 75:36-39.

Ipele Eleeketa: Baasi Eran; won n pe ni oruko yi nitori pe o jo ekiri eran, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

"... فَخَلَقْنَا الْعَلَقَةَ مُضْغَةً فَخَلَقْنَا الْمُضْغَةَ عِظَامًا...

''... Leyin naa A so eje didi naa di baasi eran, leyin naa A so baasi eran naa di eegun ...'' Q 23:14.

Ni ipele yii ni igbekale ati iyaworan omoniyan ti ma n bere titi yoo fi pari ni ideda. Olohun ti ola Re ga so pe:

إِنَّ اللَّهَ لَا يَخْفَى عَلَيْهِ شَيْءٌ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ (5) هُوَ الَّذِي يُصَوِّرُكُمْ فِي الْأَرْحَامِ كَيْفَ يَشَاءُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (6)

''Dajudaju ko si oun kan ti o pamo fun Olohun ni ori ile ati ni sanmo \\ Oun ni Eni ti O da yin sinu apoluke bi O ti fe. Ko si Olohun miiran ayafi Oun, Alagbara, Ologbon.'' Q3:5-6.

Ni ipele bakan naa ni won yoo ti fe emi si i lara, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

ثُمَّ سَوَّاهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِنْ رُوحِهِ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ قَلِيلًا مَا تَشْكُرُونَ (9)

''Leyin naa O se ni dogbandogba O si fe ninu emi Re si i. O si se igboro fun yin ati awon iriran ati awon okan, die ni ope yin ti e nda.'' Q 32:9.

Alaye ti o yanju nipa iye asiko ti ipele kookan ninu awon ipele wonyi je ti waye ninu oro ni Abdullah omo Masu'd (Olohun ki o yonu si) gba wa ti o so pe: Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba wa soro, eni ti o je olododo ti awon tun gba si olododo, wi pe:

إن أحدكم ليجمع خلقه في بطن أمه أربعين يوماً نطفة، ثم يكون علقةً مثل ذلك، ثم يكون مضغة مثل ذلك، ثم يُرْسِل إليه الملك فينخ فيه الروح ويؤمر بأربع كلمات: رزقه، وأجله، وعمله، وهل هو شقيٌ أو سعيد..."

''Dajudaju won ko ideda enikookan yin jo sinu iya re fun ogoji ojo ni eni ti o wa ni ato, leyin naa yoo di eje didi fun iye ounka asiko yi bakan naa, leyin naa yoo di baasi eran fun iye ounka asiko yi bakan naa, leyin naa won yoo ran Malaika si, yoo si fe emi si lara, won yoo si pa a lase awon gbolohun merin kan; ije imu re, asiko re, ise re, se oloriire ni yoo je ni abi olori buruku ...'' (Al Bukhari ati Muslim)

 

KI NI A N PE NI EMI ?

O je nnkan ti a ni igbagbo si bibe re sugbon ti a ko foju ri, a ko mo o pelu awon eya ara ti a fi maa nmo nnkan sugbon a ni igbagbo si bibe re, a nfura mo a si nri awon oripa re. Emi je okan pataki ninu awon eri nlanla ti ntoka lori bibe Olohun Oba ti mimo n be fun. Eleyi je ida oro pada sini lenu fun awon ti won nwa eri ti won fi le mo pelu awon eya ara ti a fi maa nmo nnkan wi pe Olohun n be, leyi ti o si jepe won ni igbagbo si bibe emi, biotile jepe won ko mo o pelu awon eya ara wonyi sugbon lati ara wi pe won ri awon oripa re.

Emi je okan ninu awon koko Olohun eyi ti enikan ko mo nipa re ayafi Olohun nikansoso. Ko si anfaani fun omoniyan lati se iwadi lati mo nipa re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الرُّوحِ قُلِ الرُّوحُ مِنْ أَمْرِ رَبِّي وَمَا أُوتِيتُمْ مِنَ الْعِلْمِ إِلَّا قَلِيلًا (85)

''Ati pe won o bi o lere nipa emi. So pe: Emi n be ninu ase Oluwa mi, ati pe A ko fun yin ni imo bikose die.'' Q 17:85.

Ar ragib Al asfahani so bayi pe: ''Eleyi ni ipele eyi ti o sepe nigba ti o ba waye ninu ara obinrin ni isemi, igbera pa, ifuramo, imo, irori ati isopinya (laarin awon orisirisi nnkan) yoo di ohun ti ara (ole inu) yoo le maa se, sugbon nigba ti o ba safeku awon nnkan wonyi ni ipele yi, yoo di oku, yoo si wa bukata si ona ti won yoo fi gbe e jade …. Ipele yi ni aaye ti awon ohun ti o niise pelu emi yoo ti maa farahan, gegebi ara se je aaye ti awon oun ti o niise pelu ara yoo se maa farahan.'' (Ad dhariah ila makarimi as shariah).

 Ni ipele yi ni awon eegun yoo ti sara jo ti eran yoo si bo o, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

فَخَلَقْنَا الْمُضْغَةَ عِظَامًا فَكَسَوْنَا الْعِظَامَ لَحْمًا

''Leyin naa A so baasi eran naa di egungun, leyin naa A fi eran bo eegun.'' Q 23:14.

Olohun ti ola Re ga nso nipa itan Uzayr bayi pe:

وَانْظُرْ إِلَى الْعِظَامِ كَيْفَ نُنْشِزُهَا ثُمَّ نَكْسُوهَا لَحْمًا فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُ قَالَ أَعْلَمُ أَنَّ اللَّهَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (259)

''Si woye si awon egungun naa, bawo ni A ti to won jo po, leyin igba naa ti A si fi eran bo won'. Nigba ti o han si i, o so pe: Emi mo pe dajudaju Olohun ni agbara lori oun gbogbo.'' Q 2:259.

Ole inu yi yoo maa dagba soke titi yoo fi di asiko ti Olohun Oba Abiyi ti bu sile pe yoo jade bo sinu aye yi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِلَيْهِ يُرَدُّ عِلْمُ السَّاعَةِ وَمَا تَخْرُجُ مِنْ ثَمَرَاتٍ مِنْ أَكْمَامِهَا وَمَا تَحْمِلُ مِنْ أُنْثَى وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلْمِهِ وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ أَيْنَ شُرَكَائِي قَالُوا آذَنَّاكَ مَا مِنَّا مِنْ شَهِيدٍ (47)

''Odo Re (Olohun) naa ni a o da mimo akoko igbende pada si. Kosi eso kan ti yoo jade ninu apopo re, ko si si obinrin kan ti yoo loyun tabi ki o bimo ayafi pelu mimo Re ni. Ati pe ni ojo ti yoo pe won pe: Nibo ni awon orogun Mi wa ? Won yoo so pe: Awa jewo fun O pe, ko si eleri kan ninu wa.'' Q 41:47.

Oluwa ti ibukun ati giga n be fun ti salaye awon ipele wonyi ti ideda omoniyan yoo gba koja lati ibere re titi de ipari ninu ese oro wura Al Kurani kan pere ni nnkan ti o le ni ogorun odun merinla seyin, eleyi ti o ntoka lori bi Al Kurani ti a so kale fun Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma baa) naa se je oun iyanu ati ikonilagara. Bakan naa ni o tun n se afihan ije ododo ise ti Ojise Olohun yi (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) mu wa. Olohun ti ola Re ga so nipa re bayi pe: 

وَمَا يَنْطِقُ عَنِ الْهَوَى (3) إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْيٌ يُوحَى (4)

''Ati pe ki nso oro ife inu \\ Oun ko je (ise) kannkan bikose oun ti A ran (si i).'' Q 53:3-4

Olohun ti olaRe ga so bayi pe:

وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ سُلَالَةٍ مِنْ طِينٍ (12) ثُمَّ جَعَلْنَاهُ نُطْفَةً فِي قَرَارٍ مَكِينٍ (13) ثُمَّ خَلَقْنَا النُّطْفَةَ عَلَقَةً فَخَلَقْنَا الْعَلَقَةَ مُضْغَةً فَخَلَقْنَا الْمُضْغَةَ عِظَامًا فَكَسَوْنَا الْعِظَامَ لَحْمًا ثُمَّ أَنْشَأْنَاهُ خَلْقًا آخَرَ فَتَبَارَكَ اللَّهُ أَحْسَنُ الْخَالِقِينَ (14) ثُمَّ إِنَّكُمْ بَعْدَ ذَلِكَ لَمَيِّتُونَ (15) ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ تُبْعَثُونَ (16)

''Dajudaju Awa da eniyan lati inu eyi ti a yo ninu erupe amo \\ Leyin naa A se e ni omi logbologbo sinu aaye irorun kan \\ Leyin naa Awa so omi logbologbo naa di eje didi, leyin naa A so eje didi naa di baasi eran, leyin naa A so baasi eran naa di eegun, leyin naa A fi eran bo eegun, leyin naa A so di eda miiran kan. Ibukun ni fun Olohun, Eni ti O dara ju lo ninu awon dedadeda \\ Dajudaju leyin eleyini eyin yoo ku \\ Leyin naa ni ojo ajinde A o gbe yin dide.'' Q 23:12-16.

Olohun Onibukun Olola giga tun so ninu ese oro wura miiran pe:

يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنْ كُنْتُمْ فِي رَيْبٍ مِنَ الْبَعْثِ فَإِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ تُرَابٍ ثُمَّ مِنْ نُطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ مِنْ مُضْغَةٍ مُخَلَّقَةٍ وَغَيْرِ مُخَلَّقَةٍ لِنُبَيِّنَ لَكُمْ وَنُقِرُّ فِي الْأَرْحَامِ مَا نَشَاءُ إِلَى أَجَلٍ مُسَمًّى ثُمَّ نُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوا أَشُدَّكُمْ وَمِنْكُمْ مَنْ يُتَوَفَّى وَمِنْكُمْ مَنْ يُرَدُّ إِلَى أَرْذَلِ الْعُمُرِ لِكَيْلَا يَعْلَمَ مِنْ بَعْدِ عِلْمٍ شَيْئًا وَتَرَى الْأَرْضَ هَامِدَةً فَإِذَا أَنْزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاءَ اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ وَأَنْبَتَتْ مِنْ كُلِّ زَوْجٍ بَهِيجٍ (5) ذَلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّهُ يُحْيِ الْمَوْتَى وَأَنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (6) وَأَنَّ السَّاعَةَ آتِيَةٌ لَا رَيْبَ فِيهَا وَأَنَّ اللَّهَ يَبْعَثُ مَنْ فِي الْقُبُورِ (7)

''Eyin eniyan, ti eyin ba n be ninu iyemeji si igbende dajudaju Awa ni A se eda yin lati inu iyepe, leyin naa lati inu omi gbologbolo, leyin naa lati inu eje didi,leyin naa lati inu baasi eran, (eyi) ti A da pe ni eda ati eyi ti A ko da pe ni eda, nitori ki A le se afihan (agbara wa) fun yin. Ati pe A nfi oun ti A fe rinle sinu apo ibimo titi lo di asiko ti A so, leyin naa A o wa mu yin jade ni oponlo, leyin naa ki e le dagba. Eni ti yoo sanku yoo maa be ninu yin, eni ti A o da pada lo si ibi ki o lo emi titi di (asiko) yepere yoo maa be ninu yin to bee ti ko fi ni mo nnkankan mo, leyin ti o mo nnkan. Ire yoo ri ile ti o ti gbe pe nigba ti A ba so omi (ojo) kale lee lori, yoo yira pada yoo si gberu yoo si hu jade ninu gbogbo awon orisirisi irugbin ti o dara \\ Eyihun je bee, nitori pe dajudaju Olohun oun (Oba) Otito ati pe dajudaju Oun ni yoo ji awon oku, ati pe oun ni alagbara lori gbogbo nnkan \\ Ati pe dajudaju akoko naa nbo nwa ti ko si tabi sugbon ninu re; ati pe dajudaju Olohun yoo gbe eni ti n be ninu saare dide.'' Q 22:5-7.

Ododo ni oro Olohun ti O so bayi pe:

سَنُرِيهِمْ آيَاتِنَا فِي الْآفَاقِ وَفِي أَنْفُسِهِمْ حَتَّى يَتَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُ الْحَقُّ أَوَلَمْ يَكْفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ (53)

''A o fi awon ami wa han won no oferefe ati ninu ara won, titi yoo fi han si won pe ododo ni. Nje ko ha to; pe Oluwa re ni eleri lori gbogbo nnkan.'' Q 41:53.

Ojogbon Keith Moore so ninu iwe re – Idagbasoke Omoniyan- (The developing human) wi pe: ''Mi o ri inira kannkan biotilewu ki o mo nibi ki ngba wi pe dajudaju Al Kurani oro Olohun nii se, nitori pe alaye ti okun keke nipa ole inu ti n be ninu Al Kurani naa ko seese ki o waye lati ara imo ijinle ti n be ni ogorun odun keje, ona abayo kan pere ti o ba lakaye mu naa ni pe awon alaye wonyi je eyi ti Olohun so kale fun Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) ''.

 

 

 

KI NI PAAPAA OUN TI NJE ILE AYE?

 Olohun Oba Abiyi ti ola Re gbongbon salaye paapaa oun ti nje ile aye, O si je ki o ye wa pe o da gegebe ojiji lasan ni. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

اعْلَمُوا أَنَّمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ وَزِينَةٌ وَتَفَاخُرٌ بَيْنَكُمْ وَتَكَاثُرٌ فِي الْأَمْوَالِ وَالْأَوْلَادِ كَمَثَلِ غَيْثٍ أَعْجَبَ الْكُفَّارَ نَبَاتُهُ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَاهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَكُونُ حُطَامًا وَفِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ شَدِيدٌ وَمَغْفِرَةٌ مِنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٌ وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا مَتَاعُ الْغُرُورِ (20)

''Ki e mo amodaju pe igbesi aye yi je ere ati awada ati oso ati ise iyanran ni aarin ara yin ati iwa ini si ninu owo ati awon omo. (Gbogbo re) da gegebi esu ojo ti irugbin re ko idunu ba agbe, leyin naa ti o tun ro iwo yoo si ri i pe o pon leyin naa yoo di oun ti o run. Ati pe iya ti o le n be ni orun ati aforijin lati odo Olohun ati iyonu (Re). Nitori naa igbesi aye ko je kinikan ju igbadun itanje lo.'' Q 57:20.

Bakan naa ni pe o je adanwo ati pe igbadun re je ere lasan ti eniyan gbodo sora fun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

فَمَا أُوتِيتُمْ مِنْ شَيْءٍ فَمَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَمَا عِنْدَ اللَّهِ خَيْرٌ وَأَبْقَى لِلَّذِينَ آمَنُوا وَعَلَى رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ (36)

''Nitori naa ohunkohun ti A ba fun yin nitori igbadun aye nikan ni, ati pe oun ti n be ni odo Olohun ni o dara ju ti yoo si seku fun awon eni ti won gbagbo ni ododo ti won si fi ara ti Oluwa won.'' Q 42:36.

Eyi ti o pataki ju lo naa ki igbesi aye yi je ategun fun igbesi aye ti orun, nitori pe ile aye da gegebi ogba oko ti igbesi aye ti orun si je aaye ti a o ti kore oun ti a ba gbin, gbogbo oun ti omoniyan ba se ni ile aye yi ni yoo gba esan re ti o ba ni orun, ti o ba se daradara yoo gbesan rere ti o ba si se aburu yoo gba esan aburu. Lori eleyin ni Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَاضْرِبْ لَهُمْ مَثَلَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَاءٍ أَنْزَلْنَاهُ مِنَ السَّمَاءِ فَاخْتَلَطَ بِهِ نَبَاتُ الْأَرْضِ فَأَصْبَحَ هَشِيمًا تَذْرُوهُ الرِّيَاحُ وَكَانَ اللَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ مُقْتَدِرًا (45) الْمَالُ وَالْبَنُونَ زِينَةُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَالْبَاقِيَاتُ الصَّالِحَاتُ خَيْرٌ عِنْدَ رَبِّكَ ثَوَابًا وَخَيْرٌ أَمَلًا (46)

''Ati pe fi apejuwe ile aye lele fun won o da bi omi ti A so kale lati sanmo, leyin naa ti o ro po mo irugbin ile, leyin naa o si di gbigbe, ategun sit u u ka. Olohun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan \\ Awon dukia ati awon omo yin je oso igbesi aye; sugbon oun ti yoo seku ni ise rere, o dara ni esan ni odo Oluwa re o si dara ni ireti.'' Q 18:45-46.

 Lati ara bi ile aye yi se yepere to, Olohun maa nyonda (daradara) re fun ati onigbagbo ododo ati alaigbagbo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّ اجْعَلْ هَذَا بَلَدًا آمِنًا وَارْزُقْ أَهْلَهُ مِنَ الثَّمَرَاتِ مَنْ آمَنَ مِنْهُمْ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ قَالَ وَمَنْ كَفَرَ فَأُمَتِّعُهُ قَلِيلًا ثُمَّ أَضْطَرُّهُ إِلَى عَذَابِ النَّارِ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ (126)"

''Nigbati Ibrahima si wi pe: Oluwa se ilu yi ni ilu ifayabale, ki O si pese eso fun awon eniyan inu re eni ti o ba gba Olohun gbo ninu won ati ojo ikehin. Oun (Olohun) wi pe: Ati eni ti o ba sai gbagbo, Emi yoo fun ni igbadun fun igba die, leyin igbanaa, Emi yoo dari re sibi iya ina, apadasi buburu ni eyi je.'' Q 2:126.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

كُلًّا نُمِدُّ هَؤُلَاءِ وَهَؤُلَاءِ مِنْ عَطَاءِ رَبِّكَ وَمَا كَانَ عَطَاءُ رَبِّكَ مَحْظُورًا (20) انْظُرْ كَيْفَ فَضَّلْنَا بَعْضَهُمْ عَلَى بَعْضٍ وَلَلْآخِرَةُ أَكْبَرُ دَرَجَاتٍ وَأَكْبَرُ تَفْضِيلًا (21)

''Awon wonyi (ti n wa oore aye) ati awon wonyi (ti n wa oore orun) gbogbo ni a n se oore (aye) fun lati inu ore Oluwa re. ore Oluwa re ko se e so di eewo \\ Wo bi A se fi apakan won ju apakeji lo. Dajudaju orun ni o tobi ju lo ni ipo, ju lo lore aju lo.'' Q 17:20-21.

Sahl omo Saa'd (Olohun ki o yonu si) so pe: ''Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) koja ni Dhu l hulayfa ni o ba ri oku eran kan ti o ka ese soke, bayi ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe: Se e ri bi oku eran yi se wa ti ko je nnkankan lodo olowo re mo? Won so pe: beeni. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa so pe: Mo fi Eni ti emi mi n be lowo Re bura wi pe ile aye yi yepere lodo Olohun ju bi oku eran yi se yepere lodo olowo re lo, ti o ba sepe ile aye yi se deedee iye efon lodo Olohun ni alaigbagbo ko ba ti ri gee omi kan mu nibe.'' (Al Mustadrak).

Olohun ti ibukun ati ola n be fun n seni lojukokoro lori isemi alikiyamo ati idera re, Olohun so bayi pe:

بَلْ تُؤْثِرُونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا (16) وَالْآخِرَةُ خَيْرٌ وَأَبْقَى (17)

''Sugbon aye ni e wa maya \\ Bee si ni orun lo dara ju lo ti yio si maa be titi (se ku gbere).'' Q 87:16-17.

Bakan naa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

والله ما الدنيا في الآخرة إلا مثل ما يجعل أحدكم إصبعه هذه وأشار يحيى بالسبابة في اليم فلينظر بم يرجع

''Ile aye ko je nnkankan legbe oun ti n be ni orun bikose gegebi apejuwe ki enikookan ninu yin ti ika ilabe re bo inu omi agbami odo, ki oun naa woye si oun ti yoo mu jade.'' (Muslim).

 Igbadun ti o wa ni orun ko si fun enikannkan ayafi awon esa ninu awon eda Olohun, awon eni ti Olohun Oba Abiyi nyonu si. Olohun ti ola Re ga so pe:

فَأَمَّا مَنْ أَعْطَى وَاتَّقَى (5) وَصَدَّقَ بِالْحُسْنَى (6) فَسَنُيَسِّرُهُ لِلْيُسْرَى (7) وَأَمَّا مَنْ بَخِلَ وَاسْتَغْنَى (8) وَكَذَّبَ بِالْحُسْنَى (9) فَسَنُيَسِّرُهُ لِلْعُسْرَى (10)

''Ki e ri eni ti ntoore ti o si ipaya (Olohun) \\ Ti o gba oun rere si ododo \\ Nitori naa A maa se ise rere ni irorun fun - un \\ Ki e ri eni ti o se ahun ti o ro pe oun to tan \\ Ti o si pe ohun ti o dara ni iro \\ Nitori naa A o se ise aburu ni irorun fun – un.'' Q 92:5-10.

Eleyi ko tumo si pe ki eniyan pa ile aye ati igbadun awon ohun ti o dara ti Olohun se ni eto ninu re ti, ninu jije ati mimu ati aso wiwo pelu igbeyawo. Olohun ti ola Re ga so pe:

قُلْ مَنْ حَرَّمَ زِينَةَ اللَّهِ الَّتِي أَخْرَجَ لِعِبَادِهِ وَالطَّيِّبَاتِ مِنَ الرِّزْقِ...

''Wi pe: Tani eni ti o se leewo oso ti Olohun, eyiti O mu jade fun awon eru Re, awon oun ti o daradara ni ipese?...'' Q 7:32.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) naa tun so pe:

المؤمن القوي خير وأحب إلي الله من المؤمن الضعيف وفي كل خير احرص على ما ينفعك واستعن بالله ولا تعجز وإن أصابك شيء فلا تقل لو أني فعلت كان كذا وكذا ولكن قل قدر الله وما شاء فعل فإن لو تفتح عمل الشيطان"

''Onigbagbo ododo ti o lagbara o lore lodo Olohun si feran re ju onigbagbo ododo ti o je ole lo, bio tile jepe awon mejeeji ni oore n be lara won, maa se ojukokoro lori oun ti yoo se o ni anfaani, si maa wa iranlowo Olohun, ki o mo kagara, ti nnkankan ba sele si o ma se maa so pe; ti o ba sepe mo se bayi bayi ni bayi ni ko ba se ri, sugbon dipo bee wi pe; ipebubu Olohun (leyi) oun ti O ba fe nikan ni yoo maa se, nitori pe imaa wi gbolohun '' ti o ba sepe'' o ma nsi ilekun sile fun ise esu ni.'' (Muslim).

Eyi ti esin Olohun nfe lodo omoniyan ninu isemi aye oun naa ni iwotun wosi. Olohun ti ola Re ga so pe: 

وَلَا تَجْعَلْ يَدَكَ مَغْلُولَةً إِلَى عُنُقِكَ وَلَا تَبْسُطْهَا كُلَّ الْبَسْطِ فَتَقْعُدَ مَلُومًا مَحْسُورًا (29)

''Ati pe ki o ma se di owo re mo orun ati ki o ma si te sile (owo naa) tite sile patapata, ki o ma di eni eebu ti nnkan yoo tan lowo re.'' Q 17:29.

 

 

 

IDI PATAKI TI WON FI DA OMONIYAN ATI ALIJONNU

Dajudaju idi pataki ti won fi da omoniyan ati alijonnu naa ni lati maa josin fun Olohun nikansoso, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنْسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ (56) مَا أُرِيدُ مِنْهُمْ مِنْ رِزْقٍ وَمَا أُرِيدُ أَنْ يُطْعِمُونِ (57) إِنَّ اللَّهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ (58)

''Ati pe Emi ko se ed eniyan ati alijonnu lasan ayafi ki won le maa sin Mi \\ Emi ko fe ese kan lodo won Emi ko si fe ki won fun Mi ni ounje \\ Dajudaju Olohun ni Olupese Alagbara ti o le.'' Q 51:56-58.

Won ko da omoniyan lasan (lai nidi), Olohun ti ola Re ga so ninu Re bayi pe:

أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ (115) فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ (116)

''Nigba naa, se e ha ro pe asan ni A da yin fun ni ati pe A ko ni dayin pada si odo Wa ni bi? \\ Olohun si ga lola, Oba ododo ko si Olohun miiran ayafi Oun, Oluwa oni Ite ola Alaponle.'' Q 23:115-116.

Olohun Oba ti ibukun ati ola giga n be fun, ran awon Ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) si awon eniyan ni asiko kan si ekeji, ki won le salaye fun awon eniyan ki won si to won sona losi ona ti o duro deeedee eyi ti o je okufa riri iyonu Olohun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

كَانَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً فَبَعَثَ اللَّهُ النَّبِيِّينَ مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ وَأَنْزَلَ مَعَهُمُ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ لِيَحْكُمَ بَيْنَ النَّاسِ فِيمَا اخْتَلَفُوا فِيهِ وَمَا اخْتَلَفَ فِيهِ إِلَّا الَّذِينَ أُوتُوهُ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ فَهَدَى اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا لِمَا اخْتَلَفُوا فِيهِ مِنَ الْحَقِّ بِإِذْنِهِ وَاللَّهُ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ إِلَى صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ (213)

''Gbogbo awon eniyan je iran kansoso; Olohun gbe awon Anabi dide ni olujihin rere ati olukillo ati pe Oun si so kale fun won Tira naa pelu ododo ki O ba se idajo laarin awon eniyan nipa oun ti won se iyapa enu si, enikannkan ko si se iyapa enu nipa re ayafi awon ti A fi fun leyin ti ododo wa ba won niti ilara laarin ara won. Olohun to awon ti o gbagbo si ona nipa oun ti won se iyapa enu si ni ti ododo pelu ase Re, Olohun A maa fi eni ti O ba fe mo ona taara.'' Q 2:213.

Eleyi nlo bee titi Olohun fi gbe Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dide ni opi awon Ojise, eni ti Olohun gbe dide ni ojise fun gbogbo agbaye. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا كَافَّةً لِلنَّاسِ بَشِيرًا وَنَذِيرًا وَلَكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ (28)

''Ati pe Awa ko ran o nise ayafi si gbogbo eniyan ni olufunni niro idunu ati ni olukilo, sugbon opolopo eniyan ko mo.'' Q 34:28.

Paapaa ojuse eyi ti won tori da omoniyan je eyiti o fojuhan gbangba ti o si ni imonu; oun naa si ni ijosin fun Olohun Oba Adeda nikansoso. Enikeni ti o ba lo igbesi aye re fun oun ti won tori re da a, iru eni bayi naa ni o se oriire ni paapaa oriire koda ki o je alaini ninu eto isemi aye. Ni idakeji, enikeni ti o ba lo igbesi aye re fun oun ti o yato si oun ti won tori re da a, yoo kan wahala bakan naa ni pe idaamu ati ifun pinpin emi yoo si maa be fun, oriire yoo si jina si, koda ki gbogbo oun igbadun aye korajo sodo re. olohun ti ola Re ga so bayi pe:

فَمَنِ اتَّبَعَ هُدَايَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشْقَى (123) وَمَنْ أَعْرَضَ عَنْ ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنْكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَى (124)

''Eni ti o ba tele ona Mi naa (oluware) ko ni sina beeni ko ni se oriburuku \\ Eni ti o ba seri kuro nibi iranti Mi, dajudaju igbesi aye inira ni yoo wa fun un, A o si gbe dide ni ojo ajinde ni afoju.'' Q 20:123-124.

Ni paapaa, won ko da eyikeyi ninu gbogbo eda ti o wa ninu agbaye yi bikose nitori nnkankan pataki tabi nitori anfaani kan, yala a mo eleyi tabi a ko mo o. olohun ti ola Re ga so bayi pe; 

وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاءَ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا بَاطِلًا ذَلِكَ ظَنُّ الَّذِينَ كَفَرُوا فَوَيْلٌ لِلَّذِينَ كَفَرُوا مِنَ النَّارِ (27)

''Ati pe Awa ko da sanmo ati ile ati oun ti o wa ni agbede meji won lasan. Ero aawon ti ko gbagbo niyen. Nitori naa egbe ni fun awon ti ko gbagbo ninu ina (ti won yoo wo).'' Q 38:27.

Ati pe ijosin ododo eyi ti o wa fun Olohun nikan duro lori imaa tele awon ase re pelu jijina si awon oun ti o ko ni ibamu si oun ti O se l'ofin. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَأَنَّ هَذَا صِرَاطِي مُسْتَقِيمًا فَاتَّبِعُوهُ وَلَا تَتَّبِعُوا السُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمْ عَنْ سَبِيلِهِ ذَلِكُمْ وَصَّاكُمْ بِهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ (153)

''Ati pe eyi ni ona Mi ti o to nitori naa e tele e, e ma se tele awon ona (miiran) ki e ma ba yapa kuro ni oju ona Re. Eyi ni O pa lase fun yin ki e ba le beru.'' Q 6:153.

Ilana ofin Olohun gbodo je eyi o jinna si ife inu omoniyan, awon ti won ma nso nipa Olohun oun ti ko se ni ilana yala won moomo ni tabi o seesi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُلْ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَالْإِثْمَ وَالْبَغْيَ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَأَنْ تُشْرِكُوا بِاللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا وَأَنْ تَقُولُوا عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ (33)

''Wi pe: iba oun ti Olohun mi se leewo ni iwa ti ko mo, eyiti o han ninu won ati eyiti o pamo, ati ese ati iwa ida ota sile, ati pe ki e tun maa ba Olohun wa orogun eyiti Oun ko so idi pataki kan kale fun, ati pe ki e maa so oun ti e ko ni mimo nipa re mo Olohun.'' Q 7:33.

 

 

 

IPARI

Gbogbo oun ti n be ninu aye yi ni o je pe iku naa ni ikeyin re, ti ko si si ibuye fun eyikeyi ninu won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

كُلُّ مَنْ عَلَيْهَا فَانٍ (26) وَيَبْقَى وَجْهُ رَبِّكَ ذُو الْجَلَالِ وَالْإِكْرَامِ (27)

''Gbogbo eni ti n be ni ori ile ni yoo tan \\ Oju Oluwa re ni yoo si seku, Eni ti O tobi Alaponle.” Q 55:26-27.

Bi o ti wu ki omoniyan sapa tabi gbiyanju to lati sara fun ododo yi, ko le ri ona abayo bakan naa si pe ko le ri olugbala lori re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُلْ إِنَّ الْمَوْتَ الَّذِي تَفِرُّونَ مِنْهُ فَإِنَّهُ مُلَاقِيكُمْ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَى عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ (8)

''So pe: Dajudaju iku ti e nsa fun yoo leyin ba, leyin naa A o seri yin lo si odo Eni ti O mo koko ati gbangba, Oun yoo si se iroyin ise ti e se fun yin.'' Q 62:8.

Bakan naa nipe bi o ti wu ki omoniyan sapa to pelu awon orisirisi ona, ko le fa a (asiko iku re) seyin tabi lati sun un siwaju. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

فَإِذَا جَاءَ أَجَلُهُمْ لَا يَسْتَأْخِرُونَ سَاعَةً وَلَا يَسْتَقْدِمُونَ (34)

''Akoko n be fun onikaluku ijo kookan; nigbati akoko won ba de, won ko ni lo o lora ni wakati kan, won ko si ni je ki o siwaju re.'' Q 7:34.

Olohun ti ola Re ga nso, ni Eni ti n pe awon omoniyan ati awon alijonnu nija, pataki ju lo awon eni ti won ba n se iyemeji lori bibe Olohun Oba Adeda ti O dawon, bayi pe:

فَلَوْلَا إِذَا بَلَغَتِ الْحُلْقُومَ (83) وَأَنْتُمْ حِينَئِذٍ تَنْظُرُونَ (84) وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنْكُمْ وَلَكِنْ لَا تُبْصِرُونَ (85) فَلَوْلَا إِنْ كُنْتُمْ غَيْرَ مَدِينِينَ (86) تَرْجِعُونَهَا إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ (87)

''Kinise nigba ti emi ba de ofun \\ Ati pe nigba naa eyin o maa wo \\ Ati pe Awa sunmo ju eyin lo, sugbon e ko le ri \\ Kinise ti o je pe ti e ko ba wa labe agbara (Wa), ti e o si gbesan ise yin \\ E da (emi naa) pada ti e ba je olotito.'' Q 56:83-87.

 Bi o tile jepe nigbati iku ba de ti omoniyan si ri i ni ojukoroju, gbogbo eniyan ni yoo gbagbo nigba naa ti won yoo si gba pe ododo ni oro naa, sugbon ko ni si anfaani mo lati pada si ile aye mo lati lo se ise (rere), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

حَتَّى إِذَا جَاءَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ رَبِّ ارْجِعُونِ (99) لَعَلِّي أَعْمَلُ صَالِحًا فِيمَا تَرَكْتُ كَلَّا إِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَائِلُهَا وَمِنْ وَرَائِهِمْ بَرْزَخٌ إِلَى يَوْمِ يُبْعَثُونَ (100)

''Titi nigba ti iku ba de waba okan ninu won yoo wi pe; Oluwa mi, e dami pada \\ Ki nba le se ise rere ninu eyi ti mo ti fi seyin. Rara ko je bee, dajudaju o je oro kan ti o ti nso; gaga si n be niwaju won titi lo di ojo ti A o gbe won dide.'' Q 23:99-100.

Asiko ati aaye ti enikookan yoo ku si je oun ti Olohun ko fi imo re mo enikannkan. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّ اللَّهَ عِنْدَهُ عِلْمُ السَّاعَةِ وَيُنَزِّلُ الْغَيْثَ وَيَعْلَمُ مَا فِي الْأَرْحَامِ وَمَا تَدْرِي نَفْسٌ مَاذَا تَكْسِبُ غَدًا وَمَا تَدْرِي نَفْسٌ بِأَيِّ أَرْضٍ تَمُوتُ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ (34)"

''Dajudaju odo Olohun ni imo akoko wa, A si maa so ojo kale, O si mo oun tin n be ninu apo ibimo. Ati pe emi kan ko mo oun ti oun yoo se ni ise lola. Beeni emi kan ko mo ile wo ni oun yoo ku si. Dajudaju Olohun ni Onimimo Eni ti O mo amotan.'' Q 31:34.

Iku je iran meji; kekere ati nla, iku nla ni eyi ti emi yoo jade lara ti ko si ni pada sibe mo, nigba ti iku kekere si je oorun, eyi ti emi maa njade ni ara ti yoo si tun pada sibe leekansi pelu ase Olohun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

اللَّهُ يَتَوَفَّى الْأَنْفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَالَّتِي لَمْ تَمُتْ فِي مَنَامِهَا فَيُمْسِكُ الَّتِي قَضَى عَلَيْهَا الْمَوْتَ وَيُرْسِلُ الْأُخْرَى إِلَى أَجَلٍ مُسَمًّى إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (42)

''Olohun nmu awon emi lo ni akoko iku re ati awon ti ko ku ni oju oorun. O si nmu (emi) awon ti O pase iku le lori dani, O si nda (emi) awon elomiiran sile di asiko ti a so. Dajudaju arisami n be ninu eleyi fun awon eniyan ti o ni ironu.'' Q 39:42.

 

KINI N BE LEYIN IKU?

Dajudaju oun ti o kan leyin iku naa ni ajinde, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

ذَلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّهُ يُحْيِ الْمَوْتَى وَأَنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (6) وَأَنَّ السَّاعَةَ آتِيَةٌ لَا رَيْبَ فِيهَا وَأَنَّ اللَّهَ يَبْعَثُ مَنْ فِي الْقُبُورِ (7)

''Iyen ri bee, nitori pe dajudaju Olohun ni (Oba) Otito ati pe dajudaju Oun ni yoo ji awon oku, ati pe dajudaju Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan \\ Ati pe dajudaju akoko naa nbo wa ti ko si tabi sugbon ninu re, ati pe dajudaju Olohun yoo gbe eni ti n be ninu saree dide.'' Q 22:6-7.

Awon keferi (alaigbagbo) je eni ti ma n pe ajinde niro lati igba lailai, eleyi ko si je oun tuntun rara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

زَعَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنْ لَنْ يُبْعَثُوا قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ وَذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ (7)

''Awon eni ti won se alaigbgbo rope: (Olohun) ko ni gbe won dide. So pe: Beeni, Oluwa mi n mo fi bura, dajudaju a o gbe yin dide leyin naa a o fun yin niro oun ti e ti se. Ati pe eleyi je irorun fun Olohun.'' Q 64:7.

Leyi ti won si n sapa pelu gbogbo ona lati so awon eniyan nu pelu imaa je ki won ro pe oun ti ko rorun rara ni ajinde leyin iku. Olohun ti ola Re ga so nipa won bayi pe:

"... أَيَعِدُكُمْ أَنَّكُمْ إِذَا مِتُّمْ وَكُنْتُمْ تُرَابًا وَعِظَامًا أَنَّكُمْ مُخْرَجُونَ (35) هَيْهَاتَ هَيْهَاتَ لِمَا تُوعَدُونَ (36) إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ (37

''Oun ha n se ileri fun yi pe bi e ba ku ti eyin ti di iyepe ati egungun nigba naa ni a o mu yin jade (ni aaye) bi? \\ Ohun ti a se ni adehun fun yin, ona re jin (pupo) \\ Ko si igbesi ayekan mo ayafi eyi i a wa ninu re yi: a nku a n se emi ati pe awa ko je eni ti a o gbe dide.'' Q 23:35-37.

Won ma n se afiti isemi won ati iku won si odo adamo, eyi ti ko si ye won ni wi pe eda bi ti won ni oun naa je, Olohun ti ola Ra ga so bayi pe:

وَقَالُوا مَا هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا يُهْلِكُنَا إِلَّا الدَّهْرُ وَمَا لَهُمْ بِذَلِكَ مِنْ عِلْمٍ إِنْ هُمْ إِلَّا يَظُنُّونَ (24)

''Ati pe won so pe: ko si isemi kan mo ju igbesi aye wa yi lo; a nku a si tun n se emi, ati pe kinikan ko le pa wa re ayafi akoko, ati pe won ko ni mimo nipa eyi; won kan nro aroso ni.'' Q 45:24.

Koda awon kan ninu won tun ma n bere fun awon eri ati idaniloju ti ko rorun, ki awon to le gbagbo. Olohun ti ola Re ga so nipa won bayi pe: 

إِنَّ هَؤُلَاءِ لَيَقُولُونَ (34) إِنْ هِيَ إِلَّا مَوْتَتُنَا الْأُولَى وَمَا نَحْنُ بِمُنْشَرِينَ (35) فَأْتُوا بِآبَائِنَا إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ (36)

''Dajuadaju awon wonyi maa nso pe; \\ Kosi (iku kannkan) ayafi iku ti akoko ti awa ti ku ati pe awa ko je eni ti won maa ji dide \\ Nitori naa e mu awon baba wa wa ti eyin ba je olododo.'' Q 44:34-36.

Sugbon Olohun ti ibukun ati giga n be fun da oro pada siwon lenu pelu oro Re ti O so bayi pe:

وَقَالُوا أَإِذَا كُنَّا عِظَامًا وَرُفَاتًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ خَلْقًا جَدِيدًا (49) قُلْ كُونُوا حِجَارَةً أَوْ حَدِيدًا (50) أَوْ خَلْقًا مِمَّا يَكْبُرُ فِي صُدُورِكُمْ فَسَيَقُولُونَ مَنْ يُعِيدُنَا قُلِ الَّذِي فَطَرَكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ فَسَيُنْغِضُونَ إِلَيْكَ رُءُوسَهُمْ وَيَقُولُونَ مَتَى هُوَ قُلْ عَسَى أَنْ يَكُونَ قَرِيبًا (51) يَوْمَ يَدْعُوكُمْ فَتَسْتَجِيبُونَ بِحَمْدِهِ وَتَظُنُّونَ إِنْ لَبِثْتُمْ إِلَّا قَلِيلًا (52)

''Ati pe won so pe: Nje bi a ba ti di eegun ti o ti kefun, nje awa dajudaju a o tun gbe wa dide ni eda tuntun? \\ Wi pe: e di okuta tabi irin \\ Tabi eda kan ninu oun ti o tobi ju ninu okan yin, sibesibe won a maa wa so pe: Tani yoo da wa pada (si alaaye)? Wi pe: Eni ti O pile dayin ni akoko, sibesibe won yoo mi ori won si o won yoo si wi pe: Nigbawo ni eyini (yoo je)? Wi pe: o le je pe o ti sunmo \\ Ojo ti yoo peyin jade, ti eyin o si je E ni ipe, pelu fifi ope fun Un, eyin o wa rope e ko gbe aye ju igb die lo.'' Q 17:49-52.

Ati pe won n pe ojo ajinde ati wiwaye re ni iro, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لَا تَأْتِينَا السَّاعَةُ قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتَأْتِيَنَّكُمْ عَالِمِ الْغَيْبِ لَا يَعْزُبُ عَنْهُ مِثْقَالُ ذَرَّةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ وَلَا أَصْغَرُ مِنْ ذَلِكَ وَلَا أَكْبَرُ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُبِينٍ (3) لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَئِكَ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ (4) وَالَّذِينَ سَعَوْا فِي آيَاتِنَا مُعَاجِزِينَ أُولَئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مِنْ رِجْزٍ أَلِيمٌ (5)

''Ati pe awon alaigbagbo nso pe: akoko naa ko ni wa ba wa. So pe: Beeni, mo fi Oluwa mi bura, Olumo oun ti o pamo, dajudaju (akoko) yoo wa ba yin. Odiwon omo inaagun ko pamo fun Un ninu sanmo ati lori ile, ko si si oun ti o kere ju bee lo tabi ti o tobi ayafi ki o maa be ninu tira kan ti o han gbangba \\ Ki o le ba san esan fun awon ti o gbagbo ni ododo ti won si se ise rere awon elewonni ti won ni aforijin ati ese ti o dara \\ Ati pe awon eni ti won sagbara lati ko agar aba awon ami Wa, awon wonyi ni iya buburu eleta elero n be fun.'' Q 34:3-5.

Ni ojo yi ni Olohun yoo gbe gbogbo eda dide, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

مَا خَلْقُكُمْ وَلَا بَعْثُكُمْ إِلَّا كَنَفْسٍ وَاحِدَةٍ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ (28)

''Dida yin ati gbigbe yin dide ko je kinikan bikose gegebi emi kan soso. Dajudaju Olohun ni Olugbo (oro), Oluriran.'' Q 31:28.

Olohun yoo ko won jo ni ojo isiro ati idajo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُلْ إِنَّ الْأَوَّلِينَ وَالْآخِرِينَ (49) لَمَجْمُوعُونَ إِلَى مِيقَاتِ يَوْمٍ مَعْلُومٍ (50)"

''So pe: dajudaju awon ara isiwaju ati ero ikehin \\ Dajudaju won yoo je eni kiko jo fun asiko ojo ti a ti mo.'' Q 56:49-50.

Ko si eni ti yoo pe leyin tabi ti ko ni wa rara ninu omoniyan ni ojo naa, bere lati ori eni akoko ninu eda titi kan eni ikehin. Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَقْدِمِينَ مِنْكُمْ وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَأْخِرِينَ (24)

''Ati pe dajudaju Awa mo eni ti o siwaju ninu yin ati pe dajudaju A tun mo eni ti o maa gbeyin (ninu yin).'' Q 15:24.

Olohun yoo se isiro ise gbogbo awon eda ni ojo naa, eniyan inu won ati awon alijonnu ni ibamu si ise onikaluku. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَوْمَ تَجِدُ كُلُّ نَفْسٍ مَا عَمِلَتْ مِنْ خَيْرٍ مُحْضَرًا وَمَا عَمِلَتْ مِنْ سُوءٍ تَوَدُّ لَوْ أَنَّ بَيْنَهَا وَبَيْنَهُ أَمَدًا بَعِيدًا وَيُحَذِّرُكُمُ اللَّهُ نَفْسَهُ وَاللَّهُ رَءُوفٌ بِالْعِبَادِ (30)

''Ni ojo ti emi kookan yoo ri aridaju oun ti o se ni rere ati eyi ti o se ni aburu (ni odo ara re), yoo fe ki orere ti o jinna maa be ni aarin awon oun ati ise aburu re. Olohun funra Re nkilo (iya Re) fun yin. Olohun je Alaanu si awon eru Re.'' Q 3:30.

Olohun tun nso bayi pe:

يَوْمَ يَبْعَثُهُمُ اللَّهُ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُهُمْ بِمَا عَمِلُوا أَحْصَاهُ اللَّهُ وَنَسُوهُ وَاللَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ (6)

''Ni ojo ti Olohun yoo gbe gbogbo won dide, nigba naa yoo fun won niro nipa oun ti won ti se ni ise. Olohun ti ko o sile awon si ti gbagbe. Olohun ni Olujeri lori gbogbo nnkan.'' Q 58:6.

Ni ojo yi, eyi ti o je aaye eru, omoniyan kookan ni yoo maa bora kuro ni odo awon alasunmo ati ololufe re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

فَإِذَا جَاءَتِ الصَّاخَّةُ (33) يَوْمَ يَفِرُّ الْمَرْءُ مِنْ أَخِيهِ (34) وَأُمِّهِ وَأَبِيهِ (35) وَصَاحِبَتِهِ وَبَنِيهِ (36) لِكُلِّ امْرِئٍ مِنْهُمْ يَوْمَئِذٍ شَأْنٌ يُغْنِيهِ (37)

''Ati pe nigba ti ojo ajinde naa ba de \\ Ojo ti eniyan yoo maa sa fun omo iya re \\ Ati fun iya re ati baba re \\ Ati iyawo re ati omo re \\ Ti onikaluku eniyan ninu won, ni yoo to o ran.'' Q 80:33-37.

Bee ti e ko, nigbati poki elese eniyan ba foju kan ododo iya, yoo maa gbero ki oun fi alasunmo ati ololufe oun di iya naa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَوَدُّ الْمُجْرِمُ لَوْ يَفْتَدِي مِنْ عَذَابِ يَوْمِئِذٍ بِبَنِيهِ (11) وَصَاحِبَتِهِ وَأَخِيهِ (12) وَفَصِيلَتِهِ الَّتِي تُؤْوِيهِ (13) وَمَنْ فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ يُنْجِيهِ (14)

''Elese yoo fe ni ojo naa pe ki oun fi awon omo oun gba ara oun sile ni ojo naa \\ Ati iyawo re ati arakunrin re \\ Ati awon ebi re ti won maa ndabo bo o \\ Ati gbogbo eni ti o wa lori ile patapata, leyin naa ki won gba sile.'' Q 70:11-14.

Alamori nipa ojo yi ti pari beeni ko si anfaani fun iduna dura rara. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ أَنَّ لَهُمْ مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُ مَعَهُ لِيَفْتَدُوا بِهِ مِنْ عَذَابِ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَا تُقُبِّلَ مِنْهُمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (36)

''Dajudaju awon ti won se aigbagbo, bi o ba se pe gbogbo ohun ti n be lori ile patapata ba je tiwon ati iru re pelu lati fi gba ara won la kuro nibi iya ojo ajinde, ako ni gba a ni owo won , tiwon si ni iya eleta elero.'' Q 5:36.

Eyi ti yoo je atewogba ni ojo yi nikan ni awon ise rere, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا أَمْوَالُكُمْ وَلَا أَوْلَادُكُمْ بِالَّتِي تُقَرِّبُكُمْ عِنْدَنَا زُلْفَى إِلَّا مَنْ آمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَأُولَئِكَ لَهُمْ جَزَاءُ الضِّعْفِ بِمَا عَمِلُوا وَهُمْ فِي الْغُرُفَاتِ آمِنُونَ (37)

''Ati pe ki i se awon dukia yin, ki i si i se awon omo yin ni nnkan ti o maa mu yin sunmo Wa pekipeki afi eni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni esan ilopo wa fun nipa ohun ti won se nise. Won yo si wa ninu awon ipo giga (ninu ogba idera) pelu ifokanbale.'' Q 34:37.

Ni aaye iberu naa;

'' لَا يَنْفَعُ نَفْسًا إِيمَانُهَا لَمْ تَكُنْ آمَنَتْ مِنْ قَبْلُ أَوْ كَسَبَتْ فِي إِيمَانِهَا خَيْرًا

''... Igbagbo re ki yoo se anfaani fun emi kan ti ko ti gbagbo siwaju tabi ti ko sise rere kun igbagbo re…'' Q 6:158.

Ni asiko yi, gbogbo oun ti o ni asepo pelu awon dukia aye eleyi ti omoniyan nlo fun awon anfaani ninu isemi aye ni yoo dopin. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَقَدْ جِئْتُمُونَا فُرَادَى كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَتَرَكْتُمْ مَا خَوَّلْنَاكُمْ وَرَاءَ ظُهُورِكُمْ

''Dajudaju eyin wa ba Wa ni okookan gegebi Awa ti da yin ni akoko, eyin si fi oun ti Awa fun sile ni eyin yin. Awa ko ri awon olusipe yin pelu yin awon eni ti eyin nso pe lodo yin won je orogun (Olohun). Dajudaju isopo aarin yin ti ja, oun ti e gbe oju le ti farapamo fun yin.'' Q 6:94.

Oun ti yoo seku fun un naa ni oun ti o ti siwaju ninu awon ise yala rere ni tabi aburu. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

فَمَنْ يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًا يَرَهُ (7) وَمَنْ يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُ (8)

''Nitori naa eni ti o ba se ise rere bi omo inagun yoo ri i \\ Ati pe eni ti o ba se ise aburu bi omo inagun yoo r ii.'' Q 99:7-8.

 

KI NI ATUBOTAN OMONIYAN LEYIN IGBENDE?

Atubotan omoniyan leyin iku je okan ninu nnkan meji; ninu ki o wo ogba idera (Aljannah) tabi ki o wo ina, ko si titan fun awon mejeeji ati awon eniyan ti yoo maa wa ninu won. Iduro lati gba idajo ni ojo ajinde yoo waye lati odo (Olohun) Oba Onideede ti kii se abosi enikannkan bi o ti hu ki o mo. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَنَضَعُ الْمَوَازِينَ الْقِسْطَ لِيَوْمِ الْقِيَامَةِ فَلَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا وَإِنْ كَانَ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِنْ خَرْدَلٍ أَتَيْنَا بِهَا وَكَفَى بِنَا حَاسِبِينَ (47)

''Awa yoo fi osuwon deede lele ni Ojo Ajinde. Nitori naa, Awa ko nii se abosi Kankan fun enikan. Ki (ise) je iwon eso karda (bin – lutin) A maa mu un wa. A was i to ni olusiro.'' Q 21:47.

Olohun yoo se isiro ijo kookan ni ibamu si ilana ofin eyi ti O fi ran se si won lati ojise won. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَوْمَ نَدْعُو كُلَّ أُنَاسٍ بِإِمَامِهِمْ فَمَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ فَأُولَئِكَ يَقْرَءُونَ كِتَابَهُمْ وَلَا يُظْلَمُونَ فَتِيلًا (71) وَمَنْ كَانَ فِي هَذِهِ أَعْمَى فَهُوَ فِي الْآخِرَةِ أَعْمَى وَأَضَلُّ سَبِيلًا (72)

''Ni ojo ti A oo ma ape gbogbo eniyan pelu awon asiwaju won: nigba naa eni ti A ba fun ni iwe (ise) re ni owo otun, awon wonyen ma aka iwe won. Awa ko si nii se abosi yinkin ni fun won \\ Enikeni ti o ba je afoju ninu aye yi, (nipa Islaam) ni le aye yii ohun ni afoju ni orun o si (ti) sina julo, (ko ni mo oju ona Aljannah).'' Q 17:71-72.

Nigba ti o si jepe awon musulumi awon onigbagbo ododo ti won gba awon Ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) ni ododo, ti won si lo isemi aye won lori itele ti Olohun, pelu mimaa tele awon ase Re ati jijina si awon oun ti O ko, awon wonyi yoo wo inu ogba Aljannah eyi ti o kun fun orisiris awon idera lailai ati oriire gbere ati isemi ti ko nii tan, ni ibamu si oro Oluwa wa Oba onibukun ti ola Re ga ti o so bayi pe: 

إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي مَقَامٍ أَمِينٍ (51) فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ (52) يَلْبَسُونَ مِنْ سُنْدُسٍ وَإِسْتَبْرَقٍ مُتَقَابِلِينَ (53) كَذَلِكَ وَزَوَّجْنَاهُمْ بِحُورٍ عِينٍ (54) يَدْعُونَ فِيهَا بِكُلِّ فَاكِهَةٍ آمِنِينَ (55) لَا يَذُوقُونَ فِيهَا الْمَوْتَ إِلَّا الْمَوْتَةَ الْأُولَى وَوَقَاهُمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ (56) فَضْلًا مِنْ رَبِّكَ ذَلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (57)

''Dajudaju awon olupaya (Olohun) yoo wa ni aye ifayabale (won yoowa) ninu awon ogba idera pelu awon omi iseleru (ni isale re). won yoo maa wo aso aran felefele ati aran to nipon won yoo si maa koju sira won. \\ Bayen (ni oro won yo se ri). A si maa fi awon obinrin eleyinju ege si iyawo won \\ Won yoo maa (beere fun) gbogbo nnkan eleso ninu (ogba idere) pelu ifayabale \\ Won ko ni to iku wo nibe ayafi iku ti akoko (aye) ati pe Oun yoo so won ninu iya ina Jahimi \\ O je oore lati odo Oluwa Eleda re iyen ni erenje nla.'' Q 44:51-57

Bakanaa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so nipa idera ogba Aljannah wi pe; Olohun Oba Abiyi ti ola Re gbongbon so bayi pe; 

أعددت لعبادي الصالحين ما لا عين رأت ولا أذن سمعت ولا خطر على قلب بشر، مصداق ذلك من كتاب الله تعالى:”فلا تعلم نفس ما أخفي لهم من قرة أعين جزاءً بما كانوا يعملون”متفق عَلَيْهِ.

''Mo pese sile fun awon erusin mi eni rere awon oun ti oju ko riri, ti eti ko gbo nipa re ri, ti ko si se wuye ninu okan enikannkan ri (ti enikannkan ko ronu debe ri), eleyi si wa ni ibamu si oro Olohun ti O so pe: ''Ko si emi kan ti o mo oun ti A fi pamo fun won; ninu oun ti nmu oju tutu, ni esan oun ti won se nise.'' Q 32:17'' (Al Bukhari ati Muslim).

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun so pe:

أول زمرة تدخل الجنة على صورة القمر ليلة البدر ثم الذين يلونهم على صورة أشد كوكب درى في السماء لا يبولون ولا يتغوطون ولا يتفلون ولا يمتخطون، أمشاطهم الذهب ورشحهم المسك ومجامرهم الألوة وأزواجهم الحور العين واخلاقهم على خلق رجل واحد على صورة أبيهم ستون ذراعا"

''Awon iko Alakooko ti won yoo wo o yoo da gegebi aworan osupa ojo kerinla, leyin naa awon iko ti yoo tele won yoo da gegebi aworan irawo esa ti ntan yanranyanra ni oju sanmo, won ko ni maa to bakan naa won ko ni maa ya igbe, won ko ni maa tu ito won ko si ni maa tu kelebe (tabi fon ikun), koomu iyarun won yoo je eyi ti won fi goolu (wura) se, lofinda won yoo je eyi ti won se lati ara turari Alimisiki, ife ina turari won yoo je eyi ti won se lati ara igi akan se fun un, awon iyawo won yoo je awon eleyinju ege, awon iwa won yoo je eyi ti o ba ara won mu, ti won yoo si wa ni ibamu si aworan (giga) baba won (Adamo) eyi ti yoo je odiwon igunpa ni ona ogota.'' (Ibn Hibban).

Jabir (Olohun ki o yonu si) so pe; Mo gbo ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nso pe:

إن أهل الجنة يأكلون فيها ويشربون ولا يتفلون ولا يبولون ولا يتغوطون ولا يمتخطون” قالوا: فما بال الطعام؟ قال: ”جشاء ورشح كرشح المسك يلهمون التسبيح والتحميد كما تلهمون النفس

''Dajudaju awon ara Aljannah yoo maa je won yoo si maa mu ninu re ti won ko si ni maa tu ito, won ko ni maa to, won ko si maa ya igbe, won ko si maa tun kelebe (tabi fon ikun), won wa bere bayi pe; bawo wa ni ti ounje (ti won ba je) yoo se maa je? o si dawon lohun wi pe: igunfe ati aagun ti yoo da gegebi oorun turari Alimisiki, won yoo fi isafomo ati idupe (fun Olohun) nu won gegebi won se nu yin ni imaa mi lo soke sodo.'' (Muslim).

Zayd omo Arqam (Olohun ki o yonu si) so pe;  

: أتى النبي صلى الله عليه وسلم رجل من اليهود فقال: يا أبا القاسم ألست تزعم ان أهل الجنة يأكلون ويشربون فيها؟ فقال رسول الله صلى الله عليه وسلم:”والذي نفسي بيده ان أحدهم ليعطى قوة مائة رجل في المطعم والمشرب والشهوة والجماع”فقال له اليهودي: فإن الذي يأكل ويشرب تكون له الحاجة)، فقال رسول الله صلى الله عليه وسلم:"حاجتهم عرق يفيض من جلودهم مثل المسك فإذا البطن قد ضمر"

''arakunrin kan ninu awon yehudi wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) o si so pe; Ire baba Qaasim, se kii wa se pe iwo rope awon ara Aljannah yoo maa je won yoo si maa mu ni bi? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wi pe; '' Mo fi Eni ti emi mi n be ni owo Re bura pe, won yoo maa fun enikookan ninu won ni agbara ti o se deedee agbara eniyan ogorun nibi jije ati mimu ati ibalopo (pelu obinrin) '' ni arakunrin ba dahun wi pe; sugbon eni ti nje ti o si nmu yoo ni bukata si igbon se? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si da lohun wi pe: igbon se won yoo maa je oogun ti yoo maa jade ni ara won ti yoo si da gegebi Alimisiki, bayi ni ikun yoo si lo sile.'' (Ibn Hibban)

Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) gba wa lati odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wi pe:

ينادي مناد إن لكم أن تصحوا فلا تسقموا أبدا وإن لكم أن تحيوا فلا تموتوا أبدا وإن لكم أن تشبوا فلا تهرموا أبدا وإن لكم أن تنعموا فلا تبأسوا أبدا فذلك قوله عز وجل: "ونودوا أن تلكم الجنة أورثتموها بما كنتم تعملون"."

''Olupepe yoo so wi pe: Alafia ki o maa je tiyin (lailai) e ko ni se aisan lailai, isemi gbere ki o maa je tiyin, e ko ni ku lailai, e maa wa ni odo lo lailai, e ko si ni d'arugbo lailai, e maa je igbadun lo lailai, e ko si ni kan inira lailai, eleyi si itumo oro Olohun Oba Abiyi ti ola Re ga ti O so pe ''Awa yo sip e won pe iyen ni ogba idera ti Ajogun re fun yin nitori ohun ti e n se nise.'' Q 7:43'' (Muslim)

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se alaye eyi ti yoo kere ju lo fun awon omo Aljannah nigba ti o so bayi pe:

''Dajudaju mo mo eni ti yoo jade keyin ninu ina ati eni ti yoo wo ogba idera keyin; (oun naa ni) arakunrin kan ti yoo wo jade kuro ninu ina, ti Olohun yoo si maa so fun bayi pe; maa lo ki o lo wo ogba idera, yoo de ibi ogba naa yoo jo oun ti o ti kun ni oju re, yoo pada, yoo si so pe; Ire Oluwa mi, mo ti de ibe sugbon o ti kun, Olohun yoo tun so fun pe ki o lo wo ogba idera naa, yoo de ibe sugbon yoo tun jo oun ti o ti kun ni oju re, yoo tun pada, yoo si so pe; Ire Oluwa mi, mo ti de ibe sugbon o ti kun, Olohun yoo tun so fun pe lo wo ogba idera naa, nitori pe dajudaju oun ti yoo je ipin re da gegebi ile aye ati iru re ni ilopo mewa ni tabi o da gegebi ilopo mewa ile aye, yoo wa dahun wi pe: se O nfimi se yeye ni ti o si jepe Iwo ni Oba (ti o ni gbogbo ola). Mo ri Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti rerin titi eyin ogan re fi han sita, won so pe eleyi ni eni ti yoo kere ju lo nipo ninu ogba Aljannah.'' (Al Bukhari)

Sugbon alaigbagbo ti won nja oro Olohun niyan ti won si n pe awon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) ati awon oun ti won mu wa ni iro, inu ina ni won yoo wo ti won yoo si se gbere nibe. Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقْضَى عَلَيْهِمْ فَيَمُوتُوا وَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمْ مِنْ عَذَابِهَا كَذَلِكَ نَجْزِي كُلَّ كَفُورٍ (36) وَهُمْ يَصْطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَا أَخْرِجْنَا نَعْمَلْ صَالِحًا غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ أَوَلَمْ نُعَمِّرْكُمْ مَا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَنْ تَذَكَّرَ وَجَاءَكُمُ النَّذِيرُ فَذُوقُوا فَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ نَصِيرٍ (37)

''Ati pea won ti won saigbagbo, ina jaanamo n be fun won, Awa ko ni pa won (sinu re) amibosibosi pe won yoo ku. Awa ko sin ii gbe iya re fuye fun won. Bayen ni A se n san gbogbo awon alaigbagbo ni esan // Won yoo maa logun iranlowo ninu re pe: ”Oluwa wa, mu wa jade, nitori ki a le lo se ise rere, yato si eyi ti a maa n se.”Se Awa ko fun yin ni emi gigun lo to to fun eni ti o ba fe ko isiti lati ri lo ninu asiko naa ni? Olukilo si w aba yin. Nitori naa, e to iay wo. Ko sin ii si alaranse kan fun awon alabosi.'' Q 35:36-37.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) salaye nipa eni ti iya re yoo kere ju lo ninu ina, nigba ti o so pe:

أَهْوَنُ أَهْلِ النَّارِ عَذَابًا أَبُو طَالِبٍ، وَهُوَ مُنْتَعِلٌ بِنَعْلَيْنِ يَغْلِي مِنْهُمَا دِمَاغُهُ"

''Eni ti iya re yoo kere ju lo ninu ina naa ni Abu Talib, yoo wo bata (ina) si ese re mejeej, ti opolo re yoo si maa so kotokoto (bi omi ti nho) lati ara bata mejeeji naa.'' (Muslim)

Ninu awon oun ti yoo se alekun idera lori idera awon ara Aljannah, bakan naa ti yoo si se alekun inira lori inira ati ofo lori ofo fun awon ara inu ina, ni oun ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so nipa re, nigba ti o so bayi pe:

يؤتى بالموت كهيئة كبش أملح فينادي مناد يا أهل الجنة فيشرئبون وينظرون فيقول هل تعرفون هذا فيقولون نعم هذا الموت وكلهم قد رآه ثم ينادي يا أهل النار فيشرئبون وينظرون فيقول هل تعرفون هذا فيقولون نعم هذا الموت وكلهم قد رآه فيذبح ثم يقول يا أهل الجنة خلود فلا موت ويا أهل النار خلود فلا موت ثم قرأ: "وَأَنْذِرْهُمْ يَوْمَ الْحَسْرَةِ إِذْ قُضِيَ الْأَمْرُ وَهُمْ فِي غَفْلَة - وهؤلاء في غفلة أهل الدنيا -وَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ (39)". "

''Won yoo mu iku wa ni aworan eran agbo ti o ni iwo, olupepe yoo wa pep bayi pe: Eyin ara Aljannah, won yoo gbe orun won soke won yoo si maa wo, bayi yoo si so pe: nje e ha mo eleyi bi? Won yoo si dahun wi pe beeni, oun ni iku, nitori pe gbogbo won patapata ni o ti ri, ni yoo ba pa a, ti yoo si so bayi pe; eyin ara ogba idera; e maa se gbere lo e o ni ku mo lailai, eyin ara inu ina; e maa se gbere lo, e o ni ku mo lailai '' leyin naa ni o ka oro Olohun wi pe '' Maa kilo ojo abamo fun won, nigba ti won ti pari oro (idajo) ti awon si wa ninu ifonufora'' awon wonyi wa ninu ifonufora ile aye '' ti ko si ni gbagbo”.'' (Al Bukhari).

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun so ninu oro re miiran pe:

لا يدخل أحد الجنة إلا أري مقعده من النار لو أساء ليزداد شكرا ولا يدخل النار أحد إلا أري مقعده من الجنة لو أحسن ليكون عليه حسرة"

''Enikannkan ko ni wo ogba idera bikosepe leyin ti won ba ti fi aga ijoko re han an ninu ti o ba jepe aburu ni o se, ki o le ba lekun ni ope (fun Olohun), bakan naa enikannkan ko ni wo inu ina ayafi leyin ti won ba fi aga ijoko re han ninu ogba idera ti o ba jepe rere ni o se, ki o le je abamo fun un.'' (Al Bukhari).

Bayi ni igbesi aye ati isemi ododo ti yoo maa lo gbere yoo bere, ati pe oloriire eniyan naa ni eni ti o mura sile fun ojo naa ti o si sise fun un.

 

AWON ERI LATI INU AL KURANI TI NTOKA LORI AJINDE

Al Kurani se omoniyan ni ojuoyin ni opolopo awon aaye ninu awon ese oro re pe ki o ronu si ipile re, ati pe Eni ti O da a nigba ti ko je nnkankan tele ni ikapa lati da a pada leyin ti O so di nnkan. Olohun ti ola Re ga so pe:

وَيَقُولُ الْإِنْسَانُ أَإِذَا مَا مِتُّ لَسَوْفَ أُخْرَجُ حَيًّا (66) أَوَلَا يَذْكُرُ الْإِنْسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِنْ قَبْلُ وَلَمْ يَكُ شَيْئًا (67)

''Eniyan n wi pe: ”Se nigba ti mob a ku, won yoo tun mu mi jade laipe ni alaaye bi? // Se eniyan ko rnati pe dajudaju Awa ni A se eda re teletele nigba ti ko ti i je nnkan kan?'' Q 19:66-67.

Imaa ronu si bi Olohun se ma nye ile leyin ti o ti ku pelu mimu awon irugbin jade lati inu re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمِنْ آيَاتِهِ أَنَّكَ تَرَى الْأَرْضَ خَاشِعَةً فَإِذَا أَنْزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاءَ اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ إِنَّ الَّذِي أَحْيَاهَا لَمُحْيِ الْمَوْتَى إِنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (39)

''Ninu awon ami Re tun nip e dajudaju iwo yoo n ile ni asale. Nigba ti A bas i so omi kale le e lori, o maa rura wa, o si maa yanu (fun hihu irugbin jade). Dajudaju Eni ti O ji i, Oun ma ni Eni ti O maa so awon oku di alaaye. Dajudaju Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan.'' Q 41:39.

Imaa ronu nipa ideda awon sanmo ati ile, eleyi ti o je oun ti ideda re lagbara ju ti omoniyan lo, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَمْ يَعْيَ بِخَلْقِهِنَّ بِقَادِرٍ عَلَى أَنْ يُحْيِيَ الْمَوْتَى بَلَى إِنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (33)

''Won kon ha mo ni pe dajudaju Olohun Eni ti O da sanmo ati ile, ati pe ko si ko aare nipa dida won, O ni agbara lori ki o ji awon oku? Beeni dajudaju Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan.'' Q 46:33.

Imaa ronu si bi omoniyan se nsun ti nji, eyi ti o je apejuwe isemi leyin iku, oun naa ni won si maa ndape ni iku kekere. Olohun ti ola Re ga so abyi pe:

اللَّهُ يَتَوَفَّى الْأَنْفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَالَّتِي لَمْ تَمُتْ فِي مَنَامِهَا فَيُمْسِكُ الَّتِي قَضَى عَلَيْهَا الْمَوْتَ وَيُرْسِلُ الْأُخْرَى إِلَى أَجَلٍ مُسَمًّى إِنَّ فِي ذَلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (42)

''Olohun nmu awon emi lo ni akoko iku re ati awon ti ko ku ni oju oorun. O si nmu (emi) awon ti O pase iku le lori dani, O si nda (emi) awon elomiiran sile di asiko ti a so. Dajudaju arisami n be ninu eleyi fun awon eniyan ti o ni ironu.'' Q 39:42.

Al Aa'l omo Waail wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pelu egungun ti o ti kefun, ni o ba so bayi pe;

: يا محمد أيبعث الله هذا بعد ما أرم؟ قال:”نعم يبعث الله هذا، يميتك ثم يحييك ثم يدخلك نار جهنم”قال فنزلت الآيات:”أَوَلَمْ يَرَ الْإِنْسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِنْ نُطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُبِينٌ (77) وَضَرَبَ لَنَا مَثَلًا وَنَسِيَ خَلْقَهُ قَالَ مَنْ يُحْيِ الْعِظَامَ وَهِيَ رَمِيمٌ (78) قُلْ يُحْيِيهَا الَّذِي أَنْشَأَهَا أَوَّلَ مَرَّةٍ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ (79) الَّذِي جَعَلَ لَكُمْ مِنَ الشَّجَرِ الْأَخْضَرِ نَارًا فَإِذَا أَنْتُمْ مِنْهُ تُوقِدُونَ (80) أَوَلَيْسَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِقَادِرٍ عَلَى أَنْ يَخْلُقَ مِثْلَهُمْ بَلَى وَهُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ (81) إِنَّمَا أَمْرُهُ إِذَا أَرَادَ شَيْئًا أَنْ يَقُولَ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ (82) فَسُبْحَانَ الَّذِي بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ (83)

''Ire Muhammad, se o si ro pe Olohun yoo gbe eleyi dide leyin ti o ti kefun? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wi pe; beeni Olohun yoo gbe e dide, Yoo pa o leyin naa Yoo gbe o dide leyin naa Yoo wa fi o wo ina jahannamah'' Bayi ni oro Olohun so kale bayi pe ''Eniyan ko mo ni pe dajudaju Awa ni A da oun ni lati inu omi logbologbo? Nigba naa oun wa je alatako ti o han gbangba \\ Ati pe o se apejuwe fun Wa o si gbagbe eda re. o wa nipe; Tani yoo ji egungun ti o ti kefun \\ So pe: Oun yoo j ii dide, Eni ti O se eda re ni akoko, Oun si ni onimimo nipa gbogbo eda \\ Eni ti O mu ina jade ninu igi tutu fun yin, nigba naa ni eyin si nwa fi ko ina \\ Nje Eni ti O da sanmo ayi ile ko ha ni agbara lati da iru won? Beeni, Oun O da awon eda, (Oun ni) Onimimo \\ Oun ti o je ase Re nipe nigba ti O ba gbero nnkankan, yoo so fun un pe: Ki o je bee, nigba naa yoo si je bee \\ Nitori naa ogo ni fun Eni ti ijoba gbogbo nnkan n be ni owo Re ati pe odo Re ni a o da yin pada si.'' Q 36:77-83'' (Al Haakim).

 

BAWO NI OMONIYAN YOO SE LA NI OJO YI?

Ti o ba fe mo nipa esin ti yoo je esin asinla eyi ti yoo je atewogba ni ojo naa ti yoo si je okunfa paapaa oriire lailai leyin ike Olohun lori eda, ti yoo si tun gbeni jinna, pelu iyonda Olohun, si oroburuku ati ipayinkeke lailai, oun naa ni esin Al Islam eyi ti Olohun fi ran Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba).

 

 

KINI ITUMO ESIN AL ISLAM?

Oun naa ni esin (ilana ofin) ti Olohun so kale fun Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba), eyi ti o si je olupare fun gbogbo esin ti o siwaju re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَى وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ (33)

''(Olohun) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (esin Islaam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira (re).'' Q 9:33.

Oun naa ni esin kan soso ti yoo je atewogba lodo Olohun, gbogbo esin ti o ba yato si i lati igbati Olohun ti gbe Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dide ni ojise ko nii je atewogba lodo Olohun. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَنْ يَكْفُرْ بِهِ مِنَ الْأَحْزَابِ فَالنَّارُ مَوْعِدُهُ

''Enikeni ti ko ba gba a gbo ninu awon ijo (nasaara), yehuuhi ati osebo), nigba naa ina ni adehun re.'' Q 11:17.

Itumo re si ni, ijuwo juse sile fun Olohun, ati riro fun Un (ase Re) pelu mimaa tele e (ilana Re), ki a si mora kuro nibi ebo (imaa ba A wa orogun nibi ijosin).

Oun naa si ni esin ti awon eniyan n se idije lati wo inu re n'ijo n'ijo pelu pe ko ri iranlowo owo ati ti eniyan ti o to lati gbolongo re, ninu eyi ti ko wopo ni ki a ri enikan ki o wo inu re ki o tun wa jade kuro nibe pada.

 Ko si esin kannkan ti yoo je atewogba ni odo Olohun leyin igbati O ti gbe Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dide ni ojise leyin esin Islam. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَنْ يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَنْ يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ (85)

''Enikeni ti o bat un wa esin kan se yato si Islaam, A o nii bga a lowo re. ni Ojo Ikeyin, onitoun yo si wa ninu awon eni ofo.'' Q 3:85.

Olohun ti ola Re ga tun so bayi pe:

وَمَنْ يَكْفُرْ بِهِ مِنَ الْأَحْزَابِ فَالنَّارُ مَوْعِدُهُ

''Enikeni ti ko ba gba a gbo ninu awon ijo (nasaara), yehuuhi ati osebo), nigba naa ina ni adehun re.'' Q 11:17.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) naa so bayi pe:

والذي نفس محمد بيده لا يسمع بي أحد من هذه الأمة يهودي ولا نصراني ثم يموت ولم يؤمن بالذي أرسلت به إلا كان من أصحاب النار

''Mo fi Eni ti emi Muhammad n be ni owo Re bura pe, enikeni ti o ba gbo (ipepe) mi ninu ijo yi, yala elesin yehudi ni o je ni tabi elesin nasaaro (kirisiteni) leyin naa ti o wa papoda (ku) ni eni ti ko ni igbagbo si oun ti won fi ran mi, ayafi ki o je omo ina.'' (Muslim).

 

 

 

AWON ORIGUN IPILE FUN ILANA ESIN ISLAM

Esin Islam wa pelu awon oniranran ijosin; afenu¬se (eyi ti a nfenu so), afarase ati adisokan. Awon ijosin afenuse ati afarase ni pataki ju lo ni a n pe ni awon origun esin Islam, oun ni o je ipile eyi ti esin islam duro le lori, oun si ni a maa nwo lati se idajo lori eniyan wi pe o je musulumi tabi rara. Awon nnkan ti esin Islam gbe kale yi ko si fun lati kan gbe nnkan kale lasan fun awon musulumi lai ni itumo, bikosepe o je ona lati se afomo emi won ati lati je ki won duro deedee, ki won si le mo kanga pelu sise awon ijosin wonyi.

Bayi ni esin Islam nfe ki sise awon nnkan wonyi je okunfa atun se enikookan ati ki o je okunfa iduro deedee fun un. Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

إِنَّ الصَّلَاةَ تَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ

''Dajudaju irun kiki ni ko iwa ibaje ati iwa buburu sise (fun eda).'' Q 29:45.

Olohun ti ola Re ga tun so nipa saka yiyo pe:

خُذْ مِنْ أَمْوَالِهِمْ صَدَقَةً تُطَهِّرُهُمْ وَتُزَكِّيهِمْ بِهَا

''Gba Ore (Zakaah) ninu dukia won, ki o fi so won di eni mimo, ki o si fi se afomo tun won.'' Q 9:103

Olohun tun so nipa awe gbigba wi pe:

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ (183)

''Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se aswe ni oranyan fun yin gege bi A sese e ni oranyan fun awon ti won siwaju yin, nitori ki e le maa beru (Olohun).'' Q 2:183

Bakan naa ni Olohun tun so nipa haji wi pe:

الْحَجُّ أَشْهُرٌ مَعْلُومَاتٌ فَمَنْ فَرَضَ فِيهِنَّ الْحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي الْحَجِّ

''Hajji sise ninu awon osu ti a mo ni, nitori naa, enikeni ti o ba pinnu lati se Hajji ninu won, ko gbodo so oro isokuso, ko si gbodo se eebu beeni ko gbodo si ja ninu Hajji.'' Q 2:197

Nitori naa awon ijosin ninu esin Islam je oun ti o ni ipa ti o tobi ti o si lagbara nibi gbigbin iwa omoluwabi iwa ati alaponle sinu omoniyan ati didagba soke re, bakan naa ni o tun wa fun lati se amojuto ijokan awujo awon elesin Islam pelu asepo ti ko ni ekeji.

 

 

 

AWON ORIGUN ESIN ISLAM

1 - IJERI MEJEEJI:

Eleyi naa ni ijeri pe ''ko si oluwa miiran (ti o leto si ijosin) ayafi Olohun, pelu ijeri pe Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je erusin Olohun ati Ojise Re'' oun si ni oun ti maa nso ni di elesin Islam (musulumi) ti gbogbo awon origun yoku si duro le lori.

Itumo pe ”ko si oluwa miiran (ti o leto si ijosin) ayafi Olohun'' nipe

-  ko si adeda miiran fun ile aye yi ayafi Olohun.

-  ko si olukapa ati oludari miiran ni ile aye yi ayafi Olohun.

-  ko si ohun kan ti o leto si sise ijosin fun ayafi Olohun.

Itumo ijeri pe ''Dajudaju Muhammad Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni i se'' nipe; ini adisokan pe erusin Olohun ati ojise Re ni i se, Olohun so imisi (oro Re) kale fun un, O si pa a lase ki o mu de etigbo gbogbo awon eniyan, oun naa ni O si se ni opin awon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won), leyi ti o sepe ki yoo si ojise tabi anabi miiran ti yoo wa leyin re. Eleyi ntoka lori wi pe a gbodo tele awon ase ti o ba pa, a si gbodo gba a gbo lori oun ti o ba fun wa ni iro re, ati jijinna si awon oun o ba ko ti o si koro oju si.

 

2 - IRUN KIKI:

Eleyi ni asopo laari eru ati Oluwa re. ni gbogbo igba ti omoniyan ba ti teri sinu yodoyindin aye, ti imole igbagbo wa bere sini jo ajoreyin ninu igbaaya re, oluperun yoo perun, bayi ni imole yi yoo tun tan lakotun ti yoo si maa tesiwaju nibi ajosepo pelu Adeda re ni gbogbo igba. Wakati marun (eemarun) ni irun yi ni ojumo leyi ti awon musulumi maa nki ni apapo ni inu masalasi ayafi nigba ti idiwo kan ba yoju.

Lati ara eleyi won yoo da ara won mo, ajosepo ati ife ti o yan ju yoo si maa be ni aarin won, won yoo maa beere nipa ara won, eni ti o ba n se aisan ninu won won yoo se abewo re, eni ti o ba ni bukata kan lati gbo ninu won, won yoo ran an lowo, eni ti ibanuje kan ba n be fun ninu won, won yoo duro tii, eni ti o ba n se aseeto tabi ateewo ninu won, won yoo se isiti fun un.

Irun kiki yi je okunfa pipa gbogbo iran eleyameya re laarin awujo. Awon mususlumi yoo to lowoowo (fegbe kegbe); agbalagba inu won, omode inu won, olowo inu won, alaini inu won, abiyi inu won, eniyepere inu won, deedee ni gbogbo won nibi riro ara won sile fun Olohun ati nibi diduro niwaju Olohun, gbogbo won yoo doju ko gabasi (kibula) kansoso ni asiko kan naa.

 

3-  AZ ZAKAH (SAKA):

Oun naa ni odiwon kan ninu dukia, eyi ti musulumi oloro yoo yo, pelu idunnu ati iyonusi ni eni ti ntele ase Olohun, fun awon omo iya re ti won je alaini, talaka ati awon ti won ni bukata, lati fi gbo awon bukata won ati lati yo won kuro ni ipo atoroje. Oranyan ni o je lori musulumi ti dukia re ba pe iye ti saka wo, nitori oro ti Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ وَذَلِكَ دِينُ الْقَيِّمَةِ (5)

''A wa ko si pa won ni ase kan tayo pe ki won josin fun Allaahu (ki won je) oluse – afomo esin fun Un, oluduro deede. Ki won kirun, ki won si yo zakaah. Iyen sin i esin to yanju.'' Q 98:5.

Enikeni ti o ba tako o, eni naa ti di keferi (alaigbagbo), nitori pe o di ona mo awon eleto, gegebi awon ole awon alaini awon talaka, lati gba eto won.

Az zakah (saka yiyo) kii se owo ori, gegebi awon eniyan ti ko mo nipa esin Islam se nlero, eyi ti ijoba ilu maa ngba lowo awon ara ilu re, nitori pe ti o ba je pe owo ori ni, ko ba je oranyan lori gbogbo eni ti ngbe ninu ilu Islam yala eni ti o je musulumi ni tabi eni ti kii se musulumi. Leyi ti o si jepe ninu mojemu yiyo re ni ki eniyan je musulumi, ti o tumo si pe kii se oranyan lori eni ti kii se musulumi.

NINU AWON MOJEMU SAKA YIYO:

1. Nini odinwon owo saka, ti o tunmo si wipe ki o eniyan ni owo ti o pe ye odinwon ti Islam se aagbekale re fun yiyo saka, ti yoo si je owo ti o lekun lori awon bukata ti won je oranyan le lori ninu jije, wiwo, mimu, ati ibugbe.

2. Ki odun kan geerege koja lori dukia naa, eyikeyi dukia ti odun kan ko ba koja lori re, ko je oun ti saka wo.

Esin Islam se ounka iran awon eniyan ti a gbodo yo saka fun, eleyi wa ninu oro Olohun ti O so bayi pe: 

إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاءِ وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (60)

''Owo awon ti ore (Zakaah) wa fun ni awon talika, awon alaini, awon osise zakaah, awon ti okan wo fe gba Islaam, awon eru (fun gbigba ominira) awon onigbese, awon ti won wan i oju ogun esin ati onirin – ajo (ti agara da). Oran – aniyan ni lati odo Allaahu. Allaahu si Olumo, Ologbon.'' Q 9:60.

Odiwon re je idameji abo nini ida ogorun (2.5%). Esin Islam se yiyo re ni oranyan lati ka osi nile ninu awujo, ati wiwa oogun si aburu ti o le ti ibi osi wa gegebi ole jija, ipaniyan ati igboju ota si ijo moluwabi eni. Ati pe lati se ifilole emi iranra eni lowo laarin awon musulumi pelu imaa gbo bukata eni ti o ni bukata lati gbo ati gbigbo bukata eni ti ko ni. Bakan naa, o tun je isafomo emi oloro (olowo) kuro nibi ahun, ilahun lojukokoro ati iwa imotara eni nikan pelu ife aye ati ihunrira ninu ifekufe re, leyi ti o maa nje ki o gbagbe awon omo iya re ti won je talika ati awon alaini.

Ati pe o tun je isafomo fun okan awon talika ati awon alaini kuro nibi ibinu, keeta, ati ikorira awon olowo, eleyi nigba ti won ri won (awon olowo) ti won nyo oun ti Olohun se ni oranyan lewon lori ninu dukia won, ti won si nba won lo pelu inawo ore si won, ise daradara si won ati imaa se amojuto won.

 

4 - GBIGBA AWE RAMADANA:

Awon musulumi gbodo fi osu kan ninu odun gba awe, pelu ki won koraro nibi gbogbo oun ti o le ba awe je; gegebi jije ati mimu ati ibalopo pelu iyawo eni lati igba oye (alifajari) ba ti la titi di igba ti oorun yo wo. Eleyi kii se adadaale nilu esin Islam sugbon o je oun ti Olohun se ni oranyan lori awon ijo ti o ti siwaju. Olohun ti olaa Re ga so bayi pe:

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ (183)"

''Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se aawe ni oran – anyan fun yin, gegebi A se se ni oran anyan fun awon ti won siwaju yin, nitori ki e le maa beru (Olohun).'' Q 2:183.

 Kii se pe erongba nibi awe gbigba ni pe ki eniyan kora duro nibi awon oun ti o le ba awe je nikan, gegebi jije ati mimu, bikosepe o gbodo kora duro pelu nibi awon oun ti o le ba awe je ti a ko foju ri gegebi iro pipa, oro eyin siso, ofofo sise, ijamba sise, itannije, oro ibaje ni siso ati gbogbo awon iwa aburu miiran. Bi o tile jepe jijinna si awon iwa buruku wonyi je oranyan lori musulumi nigba ti ko gba awe tele, sugbon o je eyi ti oranyan re tun wa nipon si ni asiko awe Ramadan.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so ninu oro re bayi pe: 

من لم يدع قول الزور والعمل به فليس لله حاجة في أن يدع طعامه وشرابه

''Eni ti ko ba gbe oro koro (aburu) ati ise aburu ju sile, ko si oun ti Olohun yoo fi aije ati aimu re se.'' (Al Bukhari)

Awe gbigba je ijagun (idina) laarin emi ati awon igbadun ati ojukokoro re. Awe gbigba ni awon anfaani olowo iyebiye ninu leyi ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) salaye ninu oro Olohun ti ola Re ga ti o so bayi pe:

"كل عمل بن آدم له إلا الصيام فإنه لي وأنا أجزي به، والصيام جنة وإذا كان يوم صوم أحدكم فلا يرفث ولا يصخب فإن سابه أحد أو قاتله فليقل إني امرؤ صائم والذي نفس محمد بيده لخلوف فم الصائم أطيب عند الله من ريح المسك للصائم فرحتان يفرحهما إذا أفطر فرح وإذا لقي ربه فرح بصومه

''Gbogbo ise omo Adamo ni yoo je tire ayafi awe gbigba nikan, dajudaju Emi ni o wa fun Emi naa ni maa si san esan re. Awe gbigba je gaga (iso), nigba ti enikookan yin ba ngba awe lowo, ko gbodo maa so oro isokuso (oro ti o jemo ibalopo laarin okunrin ati obinrin), ko gbodo maa gbe ohun soke (pariwo) niti ija, sugbon ti enikan ba bu u tabi o gbe owo ija si, ki o so pe; emi je eni ti o ngba awe. Mo fi Eni ti emi Muhammad n be lowo Re bura pe; oorun ti o njade lenu alaawe o dun (dara) lodo Olohun ju oorun turari Alimisiki lo. Idunnu meji l'on be fun alaawe ti yoo maa dunnu le lori; nigba ti o ba sinu (lale) yoo dunnu ati nigba ti o ba pade Oluwa re yoo dunnu pelu awe ti o gba.'' (Al Bukhari)

Awe gbigba je oun ti o ma nje ki omoniyan ni igbonmo si ipo ti awon omo iya re ti won je alaini, talika ati awon ti won ni bukata wa, awon eniyan kan ti o jepe won ko ri ounje je bi o ti to, ti won ko ri aso wo bi o ti ye, ti won ko si ri ibugbe ti o ye gbe, eleyi yoo je ki o le maa pe iwo ati eto won, yoo si tun je ki o maa wadi nipa alamori won ati bukata won.

 

5 - HAJJI SISE:

Oun naa ni lilo si ile Olohun alaponle (ni ilu Makkah) lati se awon ise adayanri kan ni awon aaye kan ti a ya soto ni gbedeke asiko kan. Origun je oranyan lori gbogbo musulumi ti o pe ni lakaye ti o ti balaga yala okunrin ni tabi obinrin. O je oranyan ni eekan ni isemi aye omoniyan pelu pe ki onitohun ni ikapa ti owo ati ara (alafia), sugbon eni ti o ba je alaisan ti aisan kii san, ti ko si fun ni anfaani lati se ise Hajji ti o si je eni ti o lowo lowo, yoo yan elomiiran ti yoo ba se e, bakan naa ni eni ti o ba je alaini; ti ko ni ju oun ti o le gbo bukata re ati awon ara ile re lo, Hajji sise ko je oranyan fun nigba naa. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلِلَّهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ الْبَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلًا وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ الْعَالَمِينَ (97)

''Irin ajo lo si ile naa nitori ti Olohun je dandan fun eni ti o ba ni agbara ona ti o maa gba de ibe. Enikeni ti o si saigbagbo, dajudaju Olohun ni Oloro laisi gbogbo eda (ko sin i bukata si won).'' Q 3:97.

Ati pe Hajji je akojo kan ti o ga ju lo ninu esin Islam, eyi ti awon musulumi yoo korajo si aaye kan soso, ni asiko kan naa, ti won yoo si maa pe Oluwa Okansoso, ti won yoo jo wo aso kan soso, ti won yoo si jo maa se ise kan naa, ti won yoo si jo maa wi gbolohun kan naa jade lenu ''Mo njepe Re Ire Oluwa mo njepe Re, mo njepe Re ko si orogun fun O, dajudaju gbogbo ope ati idera tire nikan ni ati ola pelu, ko si orogun fun O ''.

 Eyi ti o tumo sipe ''Ire Olohun a wa si aaye yi ni eni ti ndahun ipepe Re, ati ni eni ti nrannkan iyonu Re, ati ni eni ti n se afirinle ije okansoso Re, ati pe Iwo nikan ni O leto si ijosin (ododo) ti ko si elomiiran leyin Re''.

Ko si iyato laarin olowo ati talika, ati abiyi ati eniyepere, ati eniyan funfun ati eniyan dudu, ati larubawa ati awon ti kii se larubawa, gbogbo won patapata bakan naa ni won se ri niwaju Olohun ko si iyato ni aarin won ayafi lori iberu Olohun. Eyi je ise afinrinle ije omo iya eyi ti o wa laarin awon musulumi, ati lati se erongba won ati afojusun won ni okan naa.

 

AWON ORIGUN IGBAGBO

1- IGBAGBO NINU OLOHUN

Eleyi ntoka lori ini igbagbo ninu bibe Olohun, ati pe ko si olohun kan (ti o ni eto si ijosin) leyin Re, Okansoso ni ko si orogun fun Un ko si ni alafijo, ati pe Oun ni Adeda gbogbo oun ti n be patapata, Oun si ni Oludari (gbogbo alamori) re, nnkankan ko ni maa be ayafi pelu fife Re, ohunkohun ko si le sele ayafi pelu erongba Re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ (54)

''Kiyesi i, ti Re ni dida (eda) ati ase, ibukun ni fun Olohun Oluwa gbogbo eda.'' Q 7:54.

Ko si orogun fun Un nibi ije Oluwa (Olutoju gbogbo aye), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُلْ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ (162) لَا شَرِيكَ لَهُ وَبِذَلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ (163)

''So pe: Dajudaju irun mi, eran mi (ti mo n pa), Isemi aye mi ati iku mi n je ti Olohun, Oluwa gbogbo eda // Kos i egbera fun Un. Iyen ni Won pa lase fun mi. emi sin i akoko awon musulumi (ni asiko temi).'' Q 6:162-167.

Ko si orogun fun Un nibi ije Olohun Re (Enikansoso ti o leto si ijosin), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ مِنْ رَسُولٍ إِلَّا نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدُونِ (25)

''Awa ko ran ojise kan nise siwaju re afi ki A fin imisi ranse si pe: ”Dajudaju ko si Olohun ti ijosin to si afi Emi (Olohun) Nitori naa, e josin fun Mi.'' Q 21:25.

Bakan naa ko si orogun fun Un nibi awon oruko Re ati awon iroyin Re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلِلَّهِ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَى فَادْعُوهُ بِهَا وَذَرُوا الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي أَسْمَائِهِ سَيُجْزَوْنَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ

''Ti Olohun ni awon oruko ti o dara ju lo, nitori naa e fi pe E, ki e si fi Awon ti n gbunri kuro nibi awon oruko Re ti A oo san won ni esan ohun ti won n se nise.'' Q 7:180.

Ati pe Oun nikansoso ni O leto si ijosin ti ko si elomiiran leyin Re, Oun nikan laa gbara le, Oun nikan laa toro lowo Re, a ko gbodo pe elomiiran lati mu inira kuro tabi lati mu erongba wa se ayafi Oun nikansoso, Oun nikan laa fi gbogbo oniranran ijosin sori laini ayafi, toripe Oun nikan naa ni O leto si.

Ati pe Oun ni o ni awon oruko ti o dara ju lo ati awon iroyin ti o ga ju lo, leyi ti a kogbo fori yaworan re, tabi so pe ko ri bee, tabi ki a wa afijo nnkankan fun un, Olohun mo kanga kuro ninu gbogbo abujenjenku ati adinku. Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

لَيْسَ كَمِثْلِهِ شَيْءٌ وَهُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ (11)

''Ko si kini kan bi iru re. Oun sin i olugbo oluri.'' Q 42:11.

 

2 - INI IGBAGBO NINU AWON MALAIKA

Eleyi naa ni ki a nigbagbo wi pe dajudaju Olohun ni awon Malaika repete ti ko si eni ti o mo ounka won ayafi Olohun. Olohun ti mimo ati giga n be fun da won nitori ki won le maa se ijosin fun Un, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

لَنْ يَسْتَنْكِفَ الْمَسِيحُ أَنْ يَكُونَ عَبْدًا لِلَّهِ وَلَا الْمَلَائِكَةُ الْمُقَرَّبُونَ

''Mosiih ko ko lati je eru fun Olohun. Bee naa ni awon molaaika ti won sunmo Olohun.'' Q 4:172.

Ati pe won maa n se awon ise eyi ti Olohun gbe kale fun won lati se, Olohun so nipa won bayi pe:

عَلَيْهَا مَلَائِكَةٌ غِلَاظٌ شِدَادٌ لَا يَعْصُونَ اللَّهَ مَا أَمَرَهُمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ (6)

''Awon Molaaika ti won roro, ti won le ni eso re. won ki i yapa ase Olohun nibi ohun ti O ba pa lase fun won. Won si n se ohun ti won ba pa lase fun won.'' Q 66:6.

Awon Malaika wonyi kii se akegbe Olohun won kii si se awon omo Re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَقَالُوا اتَّخَذَ الرَّحْمَنُ وَلَدًا سُبْحَانَهُ بَلْ عِبَادٌ مُكْرَمُونَ (26) لَا يَسْبِقُونَهُ بِالْقَوْلِ وَهُمْ بِأَمْرِهِ يَعْمَلُونَ (27)

''Ati pe won nso pe; Oba Ajoke aye bi omo kan. Mimo Re, beeko, erusin ni won ti A ponle \\ Won kii si gba iwaju Re pelu oro siso, awon a si maa lo ase Re (ti O ba pa won).'' Q 21:26-27.

O n be ninu awon Malaika wonyi ti Olohun fun wa niro nipa oruko won ati awon ojuse won, o si n be ninu won awon ti ko fun wa niro nipa won, sugbon oranyan ni ki a ni igbagbo ninu gbogbo won lapapo.

 

3-  INI IGBAGBO NINU AWON TIRA

Eleyi tumo si pe dajudaju Olohun ti mimo ati giga n be fun so awon Tira kale lati odo Re ni oke sanmo fun awon Ojise Re (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) lati fi jise fun awon eniyan, ninu awon Tira wonyi ni:

1-  Suhufu ti Anabi Ibrahim (ike ati ola Olohun ki o ma ba a), Al Kurani salaye die ninu awon ipile esin eyi ti o wa ninu Tira yi, nigba ti Olohun so bayi pe:

أَمْ لَمْ يُنَبَّأْ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَى (36) وَإِبْرَاهِيمَ الَّذِي وَفَّى (37) أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَى (38) وَأَنْ لَيْسَ لِلْإِنْسَانِ إِلَّا مَا سَعَى (39) وَأَنَّ سَعْيَهُ سَوْفَ يُرَى (40) ثُمَّ يُجْزَاهُ الْجَزَاءَ الْأَوْفَى (41)

''Tabi won ko fun un niro nipa oun ti o wa ninu Tira Musa \\ Ati ti Ibrahima eni ti o mu ofin Olohun se? \\ Pe aru eru (ese) kan ko le ru eru (ese) ti elomiiran \\ Ati pe ko si oun ti o wa fun eniyan ju oun ti o se nise lo \\ Ati pe ise re A o fi han laipe \\ Lehinnaa A o san an ni esan re, ni esan ti o kun rere.'' Q 53:36-41.

2 - At Taorata, oun ni Tira Mimo ti A so kale fun Anabi Musa (ike ati ola Olohun ki o ma ba a), Olohun ti ola re ga so bayi pe:

 “إِنَّا أَنْزَلْنَا التَّوْرَاةَ فِيهَا هُدًى وَنُورٌ يَحْكُمُ بِهَا النَّبِيُّونَ الَّذِينَ أَسْلَمُوا لِلَّذِينَ هَادُوا وَالرَّبَّانِيُّونَ وَالْأَحْبَارُ بِمَا اسْتُحْفِظُوا مِنْ كِتَابِ اللَّهِ وَكَانُوا عَلَيْهِ شُهَدَاءَ فَلَا تَخْشَوُا النَّاسَ وَاخْشَوْنِ وَلَا تَشْتَرُوا بِآيَاتِي ثَمَنًا قَلِيلًا وَمَنْ لَمْ يَحْكُمْ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ فَأُولَئِكَ هُمُ الْكَافِرُونَ (44)

''Dajudaju Awa ti so At Taorata kale, ona mimo n be ninu re ati imole. Awon Anabi ti won gba fun Olohun won dajo pelu re fun awon Yehudi ati fun awon alufa won agba ati awon amofin won, nitori pe a fun won ni Tira Olohun so, won si je eleri si i. E mase beru awon eniyan, e beru Mi, e mase fi owo die paro aayah (ami tabi ese oro) Mi. Eni ti ko ba dajo pelu oun ti Olohun so kale, awon eleyinni je alaigbagbo.'' Q 5:44.

3 - Az zabuur (Sabura), oun ni Tira ti won so kale fun Anabi Dawuda (ike ati ola Olohun ki o ma ba a), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

“وَآتَيْنَا دَاوُودَ زَبُورًا (163)”

'' A si fun Dawuda ni Sabura.'' Q 4:163.

4 - Al Injeel (Injila), oun ni Tira Mimo ti won sokale fun Anabi Isa (ike ati ola Olohun ki o ma ba a), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَقَفَّيْنَا عَلَى آثَارِهِمْ بِعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ وَآتَيْنَاهُ الْإِنْجِيلَ فِيهِ هُدًى وَنُورٌ وَمُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ وَهُدًى وَمَوْعِظَةً لِلْمُتَّقِينَ (46)”

''Ati pe Awa fi Anabi Isa omo Mariyama tele ipase won, ti o nje ki a mo ododo nipa oun ti o ti siwaju re ninu At taorata, A si fun un ni Injila, imona n be ninu re ati imole ti o nje ki a mo ododo nipa oun ti o ti siwaju re ninu At taorata, o si je imona ati isisti fun awon oluberu (Olohun).'' Q 5:46.

O je orayan lori musulumi ki o ni igbagbo si gbogbo awon Tira ti a so kale lati sanmo lai dakan si, ki o gbagbo pe gbogbo re odo Olohun ti ola Re ga ni o ti wa. Yato si awon eyi ti n be lode loni (ti o jepe won ti di atowoda), sugbon ti a ba ri awon Tira wonyi ti ko si afikun tabi ayokuro nibe, oranyan ni ki mususlumi gba pe odo Olohun ni o ti wa sugbon kii se oranyan le lori ki o lo oun ti n be ninu re bakan naa awon ti won tele e, nitori pe won ko so tira yi kale bikose fun awon ijo kan ti won semi ni asiko kan gbogi. Anabi Isa (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) so ninu oro re pe: 

''A ko ran mi bikose si awon aguntan ile Isireli ti o nu.'' Mathew 15:24.

Ati pe Al Kurani Alaponle ti salaye die ninu oun ti o wa ninu Injila, ninu re ni iro nipa gbigbe dide Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma baa), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

“وَرَحْمَتِي وَسِعَتْ كُلَّ شَيْءٍ فَسَأَكْتُبُهَا لِلَّذِينَ يَتَّقُونَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَالَّذِينَ هُمْ بِآيَاتِنَا يُؤْمِنُونَ (156) الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ الرَّسُولَ النَّبِيَّ الْأُمِّيَّ الَّذِي يَجِدُونَهُ مَكْتُوبًا عِنْدَهُمْ فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنْجِيلِ يَأْمُرُهُمْ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَاهُمْ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُحِلُّ لَهُمُ الطَّيِّبَاتِ وَيُحَرِّمُ عَلَيْهِمُ الْخَبَائِثَ وَيَضَعُ عَنْهُمْ إِصْرَهُمْ وَالْأَغْلَالَ الَّتِي كَانَتْ عَلَيْهِمْ....”

''Ati pe ike Mi ti kari gbogbo nnkan. Nitori naa Emi yoo ko sile fun awon ti n beru (Mi) ti won si nyo saka ati awon ti won ni igbagbo ododo si awon ami Wa \\ Awon naa ni eni ti won ntele ti ojise naa, Anabi naa, eni ti ko mo o ko ti ko mo o ka, eni ti won ba akosile nipa re ni odo won ninu At taorata ati ninu Injila, yoo maa fooro won si iwa rere, yoo si maa ko buburu fun won, yoo si maa se awon oun ti o dara ni eto fun won, yoo si maa se awon oun ti ko dara ni eewo fun won, yoo si maa gbe awon eru ti o wuwo kuro fun won ati ajaga ti n be fun won ...'' Q 7:156-157.

5 - Al Kurani Alaponle, oranyan ni ki a ni igbagbo pe oro Olohun ni, eyi ti Jubirilu (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) mu wa fun Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba a), ati pe oun naa ni opin awon lati odo Olohun. Oun ni Olohun si fi pa gbogbo awon esin ti o ti siwaju re re, oranyan lori gbogbo omoniyan lati ni igbagbo si ati eni ti won so o kale fun, ati esin eyi ti won fi ran an.

 

4 - INI IGBAGBO NINU AWON OJISE (IKE ATI OLA OLOHUN KI O MA BA WON)

 Eyi tumo si pe ki a ni gbagbo wi pe dajudaju Olohun ti mimo n be fun ti ola Re si ga sesa ninu awon eda Re awon eniyan kan ti O si se won ni Ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won), O so awon Tira kale fun won pelu awon ofin lati fi jise fun awon eniyan, ki won maa ba ni awijare niwaju Olohun leyin ti O ti ran awon Ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) si won.

Olohun sesa ninu awon eda Re bakanna awon eniyan kan ti O se ni Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba), O gbe won dide lati maa pe awon eniyan lo si oju ona Re, awon Ojise ati awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wonyi po ni ounka leyi ti ko si eni ti o mo iye ounka won ayafi Olohun nikan. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِنْ قَبْلِكَ مِنْهُمْ مَنْ قَصَصْنَا عَلَيْكَ وَمِنْهُمْ مَنْ لَمْ نَقْصُصْ عَلَيْكَ

''Ati pe dajudaju A ti ran awon ojise siwaju re, awon ti A sotan won fun o ninu won ati awon ti A ko sotan won fun o ninu won.'' Q 40:78.

Ati pe dajudaju abara (eniyan) ni gbogbo awon Ojise ati awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) wonyi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ إِلَّا رِجَالًا نُوحِي إِلَيْهِمْ...."

''Ati pe Awa ko ran enikan nise siwaju re ayafi awon okunrin, A ran se si won...'' Q 12:109

Olohun ti ola Re ga so nigba ti O nsoro nipa Anabi Isa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) bayi pe:

مَا الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِ الرُّسُلُ وَأُمُّهُ صِدِّيقَةٌ كَانَا يَأْكُلَانِ الطَّعَامَ انْظُرْ كَيْفَ نُبَيِّنُ لَهُمُ الْآيَاتِ ثُمَّ انْظُرْ أَنَّى يُؤْفَكُونَ (75)

''Masihu Omo Mariyamah ko je nnkankan ju Ojise lo, dajudaju awon Ojise ti rekoja saaju re. Iya re si je olododo. Awon mejeeji a maa je ounje. Wo bi A ti salaye awon ami (wa) fun won leyinna tun wo bi won se seri kuro (nibi ododo).'' Q 5:75.

Oranyan ni o je ki a ni igbagbo si gbogbo won lapapo, enikeni ti o ba ni igbagbo si apakan won ti o si se aigbagbo si apakeji, o ti di alaigbagbo o si ti jade kuro ninu agbo esi Islam. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّ الَّذِينَ يَكْفُرُونَ بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ وَيُرِيدُونَ أَنْ يُفَرِّقُوا بَيْنَ اللَّهِ وَرُسُلِهِ وَيَقُولُونَ نُؤْمِنُ بِبَعْضٍ وَنَكْفُرُ بِبَعْضٍ وَيُرِيدُونَ أَنْ يَتَّخِذُوا بَيْنَ ذَلِكَ سَبِيلًا (150) أُولَئِكَ هُمُ الْكَافِرُونَ حَقًّا وَأَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا مُهِينًا (151)

''Dajudaju awon ti ko gba Olohun gbo ati awon Ojise Re ti won si nfe lati fi opinya si aarin Olohun ati awon Ojise Re ti won si nwi pe; Awa gba apakan gbo (ninu awon Ojise) awa ko si gba apakan gbo; won si nfe lati mu oju ona kan laarin (mejeeji) yi \\ Awon wonyi ni alaigbagbo ni ododo, A si ti pese iya elete fun awon alaigbagbo.'' Q 4:150-151.

Eni akoko ninu awon Ojise wonyi naa ni Nuha nigba ti eni ikeyin ninu won si je Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba won).

 

5 - INI IGBAGBO NINU OJO IKEYIN

Oun naa ni pe ki a ni igbagbo wi pe dajudaju ile aye yi yoo dopin ni ojo kan pelu gbogbo oun ti n be ninu re, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

كُلُّ مَنْ عَلَيْهَا فَانٍ (26) وَيَبْقَى وَجْهُ رَبِّكَ ذُو الْجَلَالِ وَالْإِكْرَامِ (27)"

''Gbogbo eni ti o wa lori ile ni o maa tan // O si maa se ku oju Oluwa re, Atobi , Alapon – onle.'' Q 55:26-27.

Pelu nini igbagbo ninu pe isemi kan n be ninu saare eyiti awon onigbagbo ododo yoo maa gbadun nibe ti awon alaigbagbo ati awon olutako ti Olohun yoo si maa jeya nibe. Bakan naa, ini igbagbo si ajinde, pe Olohun yoo gbe gbogbo eda patapata dide ni ojo naa lati se isiro ise onikaluku ati san enikookan ni esan ise re. Yoo san esan fun awon enirere ni ibamu si daradara ti won se, igbagbo won ati itele awon ojise won, yoo si je awon alaburu ni iya ni odiwon aburu ti won se pelu aigbagbo won ati iyapa awon ojise won.

Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

زَعَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنْ لَنْ يُبْعَثُوا قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ وَذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ"

''Awon to saigbagbo lero pe A o nii gbe won dide. So pe: Bee ko, mo fi Oluwa mi bura dajudaju won yoo gbe yin dide. Leyin naa, Won yoo fun yin ni iro ohun ti e se nise. Iyen si je irorun fun Olohun.'' Q 64:7.

Bakan naa ni ini igbagbo si pe Olohun yoo ko awon eda jo si oju kan. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّ يَوْمَ الْفَصْلِ كَانَ مِيقَاتًا (17)

''Dajudaju ojo ipin (eda) si otooto, o je ohun ti o ni akoko kan ni pato.'' Q 78:17.

Pelu ini igbagbo si pe gbogbo eda ni yoo seri si odo Olohun, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَعُرِضُوا عَلَى رَبِّكَ صَفًّا لَقَدْ جِئْتُمُونَا كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ بَلْ زَعَمْتُمْ أَلَّنْ نَجْعَلَ لَكُمْ مَوْعِدًا

''A o si ko won wa siwaju Olohun re nijo-nijo, (Olohun yoo wi pe): Dajudaju eyin wa ba wa (nisinsinyi) gegebi A ti da yin ni akoko ri. Oro ko ri bee, se e rope A ko fun yin ni adehun akoko kan.'' Q 18:48.

Ati ini igbagbo si ibeere eyi ti won yoo bi enikookan eda ni ojo naa, Olohun ti ola re ga so bayi pe:

وَقِفُوهُمْ إِنَّهُمْ مَسْئُولُونَ (24) مَا لَكُمْ لَا تَنَاصَرُونَ (25) بَلْ هُمُ الْيَوْمَ مُسْتَسْلِمُونَ (26)

''E da won duro na, dajudaju A oo bi won leere oro // kin i ko je kie ranra yin lowo // Rara (won ko le se bee. Amo) ni oni won ti juwo juse sile.'' Q 37:24-26.

Bakanna ini igbagbo pe awon eya ara omoniyan yoo jeri (gbe e tabi le lori), Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

حَتَّى إِذَا مَا جَاءُوهَا شَهِدَ عَلَيْهِمْ سَمْعُهُمْ وَأَبْصَارُهُمْ وَجُلُودُهُمْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (20) وَقَالُوا لِجُلُودِهِمْ لِمَ شَهِدْتُمْ عَلَيْنَا قَالُوا أَنْطَقَنَا اللَّهُ الَّذِي أَنْطَقَ كُلَّ شَيْءٍ وَهُوَ خَلَقَكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ (21) وَمَا كُنْتُمْ تَسْتَتِرُونَ أَنْ يَشْهَدَ عَلَيْكُمْ سَمْعُكُمْ وَلَا أَبْصَارُكُمْ وَلَا جُلُودُكُمْ وَلَكِنْ ظَنَنْتُمْ أَنَّ اللَّهَ لَا يَعْلَمُ كَثِيرًا مِمَّا تَعْمَلُونَ (22)

''Titi di igbati won de ibe, awon eti ati awon oju won ati awon ara won yoo maa jeri le won lori nipa oun ti won se \\ Won yoo so fun awon ara won pe: Kini se ti e jeri le wa lori? Won yoo so pe: Olohun ti nje ki gbogbo nnkan soro lo mu wa soro, ati pe Oun ni O dayin ni akoko ati odo Re ni a o dayin pada si \\ E ko si fi ara yin pamo ki awon eti yin ati awon oju yin ati awon ara yin ma le jeri leyin lori, sugbon eyin rope Olohun ko mo pupo ninu ise ti e n se.'' Q 41:20-22.

Bakan naa ini igbagbo si sise isiro ise, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

فَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ (7) فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا (8) وَيَنْقَلِبُ إِلَى أَهْلِهِ مَسْرُورًا (9)

''Nitori naa, nit i eni ti won ba fun ni iwe ise re ni owo otun re // Laipe A maa se isiro – ise (re) ni isiro irorun // O si maa pada si odo awon eniyan re (ninu Ogba Idera) pelu idunnu.'' Q 84:7-9.

Bakan naa ini igbagbo si pe omoniyan yoo gba esan re pelu wiwo yala Al jannah (ogba idera) tabi wiwo inu ina, nibi ti yoo ti maa semi gbere, Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَالْمُشْرِكِينَ فِي نَارِ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أُولَئِكَ هُمْ شَرُّ الْبَرِيَّةِ (6) إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَئِكَ هُمْ خَيْرُ الْبَرِيَّةِ (7) جَزَاؤُهُمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ جَنَّاتُ عَدْنٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ ذَلِكَ لِمَنْ خَشِيَ رَبَّهُ (8)

''Dajudaju awon ti won di keferi (wonyi) ninu awon ahlul – kitab ati awon osebo, won yoo wa ninu ina. Olusegbere ni won ninu re. awon wonyen ni eda to dara julo // Dajudaju awon ti won gbagbo ni ododo (iyen, awon musulumi), ti won si se awon ise rere, awon wonyen ni eda to dara ju lo // Esan won ni odo Oluwa won ni awon Ogba Idera gbere, ti awon odo n san ni isala re. olusegbere ni won ninu re titi laelae. Olohun yonu si won. Awon naa yonu si (ohun ti Olohun fun won). Iyen wa fun enikeni ti o ba beru Oluwa re.'' Q 98:6-8.

 

6- INI IGBAGBO SI IDAJO OLOHUN ATI IPEBUBU (KADARA)

Eleyi tumo si ini igbagbo ti o feserinle pe dajudaju Olohun ti mimo ati giga n be fun ni imo nigba gbogbo nnkan patapata siwaju ki won to maa be, pelu oun ti yoo tun maa be, leyin naa ni O wa se eda won ni ibamu si imo Re ati ipebubu Re. Olohun ti ola Re ga so bayi pe: 

وَخَلَقَ كُلَّ شَيْءٍ فَقَدَّرَهُ تَقْدِيرًا (2)

''O da gbogbo nnkan, O si yan odiwon (irisi, isemi ati ayanmo) fun ilu niwon – niwon.'' Q 25:2.

Gbogbo isele ti o ti rekoja ati awon oun ti n sele lowo ati gbogbo oun ti yoo tun maa sele ni ojo iwaju ninu aye yi ni imo re n be ni odo Olohun siwaju ki o to sele, Olohun ti mimo ati giga n be fun ni O je ki o maa sele ni ibamu si fife Re ati ipebubu Re. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

لكل شيء حقيقة وما بلغ عبد حقيقة الإيمان حتى يعلم ان ما أصابه لم يكن ليخطئه وما أخطأه لم يكن ليصيبه

''Gbogbo nnkan kookan ni o ni paapaa tire, omoniyan ko ni de paapaa igbagbo titi yoo fi daju wi pe; oun ti o ba sele si oun, ko si ninu oun ti yoo fo oun ru, oun ti o ba si fo oun ru ko si ninu oun ti yoo sele si oun.'' (Ahmad).

Eleyi ko si tako ki a mojuto awon oun ti o ye ati ki a se awon oun ti o ba ye kioje sise. Fun apere, gbogbo eni ti o ba fe bi omo, oranyan ni ki o se igbese ati ojuse ti o ye lati mu erongba re yi se, pelu pe ki o se igbeyawo, o wa seese ki igbese re yi mu eso ti o gbero jade, eyi ti se omo bibi, o si seese ki o ma ri bee ni ibamu si fife Olohun ti mimo ati giga n be fun. Nitori pe awon igbese ati sise oun ti o ye ko ni o ma nmu erongba eda se sugbon fife ati iyonda Olohun ti mimo ati giga n be fun.

Sise igbese ati sise awon oun ti o ye lati mu erongba wa se wa ninu ipebubu lati odo Olohun ti mimo ati giga n be fun, eleyi si ni itumo oro ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun awon omoleyin re nigba ti won beere lowo re pe:

يا رسول الله رقى كنا نسترقي بها وأدوية كنا نتداوى بها هل ترد من قدر الله تعالى؟ قال: ”هو من قدر الله

''Ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nje rukiyah (kika Al kurani ati awon adua Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), ti a n se ati awon oogun ti a nlo lati fi se iwosan wa le yi kadara Olohun (oun Olohun ti pebubu) pada bi? O si dawon lohun wi pe: Oun naa (sise bee) ninu kadara Olohun ni o wa.'' (Al Mustadrak).

 Ebi pipa, ongbe gbigbe ati otutu ti nmu ninu kadara Olohun ni o wa, leyi ti o si jepe awon eniyan nsapa lati kodi ebi pelu ounje jije, ati lati kodi ongbe pelu omi mimu, ati lati kodi otutu pelu dida ooru mu ara won, bayi ni won koju awon oun ti won kadara lewon lori ninu ebi, ongbe ati otutu pelu awon oun ti won kadara lewon lori ninu jije ati mimu ati dida ooru mu ara won.

Nini igbagbo ninu idajo ati kadara Olohun (ipebubu), leyin sise awon ojuse ati awon oun ti o ye ni sise, ni awon anfaani ti o po ninu, ninu re;

- Dajudaju yiyonu si oun ti o ba sele ni kadara maa nje ki eniyan ni ifokanbale ati irora ninu emi, ko ni si anfaani fun ikayasoke ati ibanuje ti o lagbara lori oun ti o ba sele yala oun ti o tee lowo ni tabi eyi ti o bo mo lowo. Ninu eyiti ko ruju ni pe ikaya soke ati idaamu emi ma n se okunfa awon orisirisi aisan, leyi ti o si jepe ini igbagbo ninu idajo kadara ati kadara Olohun lori eda, gegebi Olohun ti mimo ati giga n be fun se so, o maa n se okunfa ipare aibaleokan ati ifooro emi eyiti o maa nwaye lati ara ibanuje ati ikayasoke. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

مَا أَصَابَ مِنْ مُصِيبَةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي أَنْفُسِكُمْ إِلَّا فِي كِتَابٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ نَبْرَأَهَا إِنَّ ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ (22) لِكَيْلَا تَأْسَوْا عَلَى مَا فَاتَكُمْ وَلَا تَفْرَحُوا بِمَا آتَاكُمْ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ (23)

''Adanwo kan ko ni sele ni ori ile tabi ni inu ara yin ayafi ki o maa be ninu Tira kan siwaju ki A to mu u jade, dajudaju eyi je irorun fun Olohun \\Nitori ki e ma ba banuje lori oun ti o ti bo fun yin ati ki e ma si yo ayoju lori oun ti O fun yin, ati pe Olohun naa ko nife si gbogbo onigberaga, oniyanran.'' Q 57:22-23.

- Ipepe si imo ati iwadi awon oun ti Olohun kojo si inu ile aye yi, eleyi ntoka lori pe awon isele orisirisi eyi ti n sele si omoniyan ninu oun ti won kadara le lori, gegebi aisan eyi ti o wa ninu kadara, ti omoniyan si nwa ojutu si i pelu awon ilana itoju eyiti yoo mu kadara Alakooko kuro pelu iwadi nipa awon oun elo oogun fun itoju aisan, latara awon nnkan ti Olohun ti mimo ati giga n be fun da si ile aye yi.

- Igbefuye awon isele eyi ti nde ba omoniyan ninu awon adanwo ati ki won ba maa banuje lori oun ti o ti lo. Fun apere, ti oja ba yowo mo omoniyan lowo, leyi ti o si jepe ki a sowo ka mo jere je okan ninu awon adanwo, sugbon ti o ba jepe ibanuje ati ikayasoke ni o fi gbeyin adanwo yi, nigba naa adanwo re yoo di meji; adanwo oja ti o yowo ati adanwo ibanuje ati aibale okan. Sugbon eni ti o ba ni igbagbo ododo ninu idajo ati kadara Olohun lori eda yoo yonu si okuta (aisowo jere) akoko, nitori pe o mo pe dajudaju oun ti Olohun kadara le oun lori ni oranyan si ni ki o sele bee. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

احرص على ما ينفعك، واستعن بالله ولا تعجز، وان أصابك شيء فقل قدر الله وما شاء فعل، ولا تقل لو فإن لو تفتح عمل الشيطان” صحيح رواه مسلم

''Maa se ojukokoro lori oun ti yoo se o ni anfaani, si maa wa iranlowo Olohun ki o si ma kagara, ati pe ti ohunkohun ba sele si o maa so pe: ''Kadara Olohun ni, oun ti o ba wu U ni o maa n se'' , ma se maa so pe: ''Ti o ba sepe'' nitori pe gbolohun yi (ti o ba sepe) maa nsi ileku ise esu sile ni.'' (Muslim)

- Isopo emi pelu Olohun pelu ima maa beru nipa aburu ti o le ti odo eda wa, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so ninu oro ti o so fun Omo Abaas pe:

يا غلام إني أعلمك كلمات احفظ الله يحفظك احفظ الله تجده تجاهك إذا سألت فاسأل الله وإذا استعنت فاستعن بالله واعلم أن الأمة لو اجتمعت على أن ينفعوك بشيء لم ينفعوك إلا بشيء قد كتبه الله لك ولو اجتمعوا على أن يضروك بشيء لم يضروك إلا بشيء قد كتبه الله عليك رفعت الأقلام وجفت الصحف

''Ire omode kunrin mi, maa fi awon gbolohun nnkan mo o; maa so Olohun (pelu siso awon iwo Re), Olohun yoo si maa so iwo naa, maa so Olohun, o si maa ba A ni iwaju re, ti o ba fere beere (toro) nnkan, beere lowo Olohun, ti o ba few a iranlowo, Olohun ni ki o wa ni Oluranlowo, ki o si mo wi pe ti gbogbo ijo patapata ba korajo lati se o ni anfaani pelu nnkankan, won ko ni le se o ni anfaani ayafi pelu oun ti Olohun ti ko sile fun o. Ati pe bi won ba si korajo lati fi inira kan o pelu nnkan kan, won ko ni le fara ni o ayafi pelu oun ti Olohun ti ko sile le o lori. Won ti gbe gege (kalamu) soke takada (iwe) si ti gbe (kadara ti duro lori eda).'' (At tirmidhi).

Ati pe ini igbagbo si kadara ko ri bi awon eniyan kan se nro o si pe o je ipepe si ki a pa awon okufa ati awon ojuse ati igbese ti o ye lati se, ki a le ni aseyori lori erongba wa ti, nigbati o si jepe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti so siwaju bayi pe:

 “والذي نفسي بيده لأن يأخذ أحدكم حبله فيحتطب على ظهره خير له من أن يأتي رجلا فيسأله أعطاه أو منعه

''Ki enikookan yin mu okun (idi igi) re, ki o si loo se igi (ki o wa ru u si) eyin re (lati lo ta a) o loore fun ju ki o maa lo ba awon eniyan lo ni eni ti ntoro lowo won, yala won tile fun ni tabi won ko fun un.'' (Al Bukhari)

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) naa ni o tun so fun eni ti o bi leere wi pe; se ki ntu rakunmi mi sile ki nsi gbara le olohun, wi pe:

إعقلها وتوكل

''So o mole leyin naa ki o gbara le Olohun.'' (Ibn Hibbaan).

 

NINU AWON OUN TI WON SO NIPA ESIN ISLAM

Bernard Shaw so ninu iwe re ''Esin Islam Leyin Ogorun Odun'' wi pe: ''Dajudaju gbogbo aye patapata ni yoo tewo gba esin Islam, ti won ko ba tewo gba a pelu oruko re gangan won yoo gba pelu ayalo oruko. Asiko kan nbo ti awon Oyinbo yoo maa wo inu esin Islam leyi ti o si jepe awon asiko kan ti re koja lori awon Oyinbo ti o si jepe awon iwe oniranran ti o kun fun adapa iro orisirisi nipa esin Islam ni o kun inu won, ati pe mo ti ko iwe kan nipa Muhammad sugbon won gbesele nitori pe o tako isesi ati asa awon Oyinbo. O tun so bayi pe: Esin Islam nikan ni esin ti a ri ti o ko gbogbo daradara ti o wa ninu awon esin yoku jo, ti o si jepe a ko ri iru daradara re ninu awon esin yoku.'' (Rabihtu Muhammada wa lam akhsar Al Masihu)

 

 

 

TANI OJISE TI WON FI ESIN ISLAM RAN ?

Eni naa ni Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) Omo Abdullah oun naa si ni opin awon Ojise (ike ati ola Olohun ki o ma ba won). Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

مَا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَا أَحَدٍ مِنْ رِجَالِكُمْ وَلَكِنْ رَسُولَ اللَّهِ وَخَاتَمَ النَّبِيِّينَ وَكَانَ اللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا

''(Anabi) Muhammad ki i se baba eni kan kan ninu awon okunrin yin, sugbon (o je) Ojise Olohun ati ipekun awon Anabi. Olohun si n je onimo nipa gbogbo nnkan.'' Q 33:40

Olohun ran si gbogbo eniyan patapata, ti kii si se iran larubawa nikan ni won ran si. olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا كَافَّةً لِلنَّاسِ بَشِيرًا وَنَذِيرًا

''Awa ko si ran o nise afi si gbogbo eniyan patapatak (gegebi) oniroo – idunnu ati olukilo.'' Q 34:28

Olohun ran an nitori ki awon eniyan le so riire lapapo, ati lati le salaye fun won ona oriire ati ododo, ati lati wa won ni isora kuro nibi ona ibaje ati aburu, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ (107)

''Awa ko si fi ise imis ran o bi ko se pe ki o le je ike fun gbogbo eda.'' Q 21:107.

Igbese aye re kun fun ododo ati ifokantan, won ko ka yiye adehun tabi iro mo lowo ri, bakan naa won ko mo pelu ijanba tabi itanje, gbogbo awon ara ilu ni o mo o si eni ifokantan ti gbogbo won si maa nfi asiri won pamo si lodo, ti won si maa nfi awon dukia sodo re nigba ti won ba fe se irinajo. Gbogbo won patapata ni won gba pe olododo ni, nigbati won ti ri wi pe ododo ni gbogbo oun ti o maa nso jade lenu. Nigbati oro Olohun so kale fun un o so fun iyawo re ti se Khadijah (Olohun ki o yonu si) wi pe:

لقد خشيت على نفسي” فقالت خديجة: كلا والله ما يخزيك الله أبدا إنك لتصل الرحم وتحمل الكل وتكسب المعدوم وتقري الضيف وتعين على نوائب الحق.

''Eru nba mi, Khadijah si dahun wi pe: Oro ko ri bee, mofi Olohun bura pe; Olohun ko ni yepere re ko si ni pa o ti lailai, se kii sepe o ma nda okun ibi po ni, ti o si ma ngbo awon eniyan (pelu inanwo lewon lori), ti o si ma itore nfun awon alaini, ti o si ma n se aponle ati itoju alejo, ti o si ma nduro ti awon eniyan nibi eto won.'' (Al Bukhari ati Muslim).

Oun naa ni eni ti o pe ju lo ninu awon eniyan ni iwa ati ideda, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَإِنَّكَ لَعَلَى خُلُقٍ عَظِيمٍ (4)

'' Dajudaju iwo si wa lori iwa alapon – onle.'' Q 68:4.

 

NINU AWON OUN TI WON SO NIPA MUHAMMAD (IKE ATI OLA OLOHUN KI O MA BA)

Gbajumo elewi nni Johann Wolfgang Von Goethe ti se omo Germany so ninu iwe re pe: ''Mo se iwadi lati mo taani apere ti ko nikeji ninu omoniyan, mo ri pe Anabi iran larubawa ti se Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni.'' (Muhammad fi al aadaab al aalamiyah al munasofah).

Will Durant naa so ninu iwe re ''Itan Olaju'' wi pe: ''Ti a ba se idajo nipa pipataki eniyan ni ibamu si ilapa re lori omoniyan, a o so pe; dajudaju Ojise awon musulumi ni eni pataki ju lo ninu awon eniyan pataki ninu itan, o mu opin ba eleyameya ati ilana ebo sise, o se agbekale esin miram ti o bori esin Yehudi, esin Nasara (kirisiteni) ati esin ti n be ni ilu re lati igba ti o ti pe, esin naa je eyi ti o rorun pupo, ko mu iruju dani rara, o si je eyi ti o feserinle ti o si lagbara lati maa be titi di asiko ti a wa yi, eleyi je ikapani kan ti o lewu pupo.'' (Rabihtu Muhammada wa lam Akhsar Al Masih).

 

 

 

KINI NJE AL KURANI ?

Oro Olohun eyi ti Jubirilu (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) mu wa fun Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba). O yato si awon Tira ti o siwaju re pelu awon nnkan wonyi;

- Oun ni ikeyin gbogbo Tira ti o wa lati oke sanmo, eleyi ni o si se okunfa ki Olohun ti mimo ati giga n be fun fi la abo ara Re lorun pe Oun yoo so o, ki o le maa sekun fun omoniyan titi di igbati Olohun yoo jogun ile ati eni ti n be lori re. Ayipada kannkan ko ba Tira naa, yala afikun ni tabi iyokuro, lati igbati ti o ti sokale fun anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) titi di asiko ti a wa yi. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ (9)

''Dajudaju Awa ni A so iranti naa kale ati pe dajudaju Awa ni oluso fun un.'' Q 15:9.

- Dajudaju o je oun ti a maa nfi kika re se ijosin fun Olohun, eleyi si ki idi pataki ti won fi so kuro nibi alekun, adinku ati iyipada. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:

من قرأ حرفا من كتاب الله فله به حسنة والحسنة بعشر أمثالها لا أقول ألم حرف ولكن ألف حرف ولام حرف وميم حرف

''Enikeni ti o ba ka arafi kan ninu tira Olohun yoo gba esan daadaa kan lori re, esan daadaa kan si se deedee ilopo re lona mewa, mi o so pe '' alif lam mim '' je arafi kan sugbon '' alif '' arafi kan ni, '' lam '' arafi kan ni, '' mim '' arafi kan ni.'' (At Tirmidhi).

 -A tun ma nfi hiha re sori se ijosin fun Olohun, Omo Abaas (Olohun ki o yonu si) so pe; Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

(( إنَّ الَّذِي لَيْسَ في جَوْفِهِ شَيْءٌ مِنَ القُرْآنِ كَالبَيْتِ الخَرِبِ )) رواه أحمد , والترمذي،

''Dajudaju enikeni ti ko ba ha nnkankan sori ninu Al Kurani da gegebi ile ahoro.'' (Ahmad ati At tirmidhi).

- A tun ma nfi amojuto ati akolekan re se ijosin fun Olohun, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:

خيركم من تعلم القرآن وعلمه

''Eni ti o loore ju lo ninu yin ni eni ti o ko eko Al Kurani ti o si tun fi nko elomiiran.'' (Al Bukhari)

- Dajudaju o ko gbogbo awon ofin ti o le je okunfa ki awujo je alaponle, ti o si jepe lilo awon ofin wonyi yoo ko oriire ba gbogbo eniyan. Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَنَزَّلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ تِبْيَانًا لِكُلِّ شَيْءٍ

''Ati pe A so Tira naa kale fun o ki o le je alaye fun gbogbo nnkan.'' Q 16:89.

 -Ati pe o da gegebi iwe itan ti nsalaye bi awon Ojise ati awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se nwa ni sise ntele ati awon oun ti o sele siwon pelu awon ijo won, bere lati ori Adama (ike ati ola Olohun ki o ma ba a) titi de ori Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba a).

- Olohun so o kale ki gbogbo eniyan le soriire, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

الر كِتَابٌ أَنْزَلْنَاهُ إِلَيْكَ لِتُخْرِجَ النَّاسَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ بِإِذْنِ رَبِّهِمْ إِلَى صِرَاطِ الْعَزِيزِ الْحَمِيد"

''Alif, Lam, Ra, (Olohun ni O mo Oun ti O gba lero pelu awon harafi wonyi) eyi je Tira kan ti a so kale fun o nitori ki o le ma fi yo awon eniyan jade kuro ninu okunkun lo sinu imole pelu iyonda Oluwa won, lo si oju ona Oba ti O tobi Oba ti o ni ope.'' Q 14:1.

 

NINU AWON OUN TI WON SO NIPA AL KURANI

W. Durant so ninu iwe re ''Itan Olaju'' pe: ''Al Kuran koyekogbo lati ogorun odun merinla seyin ni ni oun ti awon musulumi nha si ori, o joko sinu lakaye won, o ndari iwa ati isesi won, o si se aleku ikapani egbeegberun lona egberun lona aimoye ogorun awon eniyan, Al Kurani nfi awon adisokan ti o rorun lele sinu emi, eyiti ko ni iruju ninu, ti ko si ni asopo pelu awon ilana ati awon ijosin ti ko lese nle ninu. Opo ninu awon adisokan je eyi ti nyoni kuro ni oko eru orisa sisin ati ebo sise.  Oun (Al Kurani) ni okunfa ilosiwaju iwa omoluwabi ati eko awon musulumi, oun ni eni ti o fi awon ipile (ilana) eto ibagbepo awujo ati eto isokan awujo lele fun won, o se won loju oyin lati maa tele awon ipile (ilana) eto ilera, o la won loju kuro nibi opolopo awon ilana ebo ati itanje ati abosi pelu ilekoko. O se atun se ipo awon eru, o si ko iyi ati eye ba emi awon eniyepere, o si fi iwontun wonsi (deedee) lole laarin awon musulumi ati ijina si ifekufe emi, leyi ti ko si si oun ti jo eleyi ni eyikeyi aaye ni orile aye ti eniyan funfun (oyinbo) ngbe ''.

IPO TI IMO WA NINU ESIN ISLAM

Esin Islam je esin ti o pepe lo sibi imo ti o si seni loju kokoro lo sibi wiwa re ti o si foju abuku wo aimokan pelu iwani nisora nibe (aimokan). Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الَّذِينَ يَعْلَمُونَ وَالَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ

''So pe: Nje awon eni ti won ni mimo ati awon eni ti won ko ni mimo dogba bi?'' Q 39:9.

Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

يَرْفَعِ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا مِنْكُمْ وَالَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ دَرَجَاتٍ

''Olohun yoo se agbega ati iyi fun awon eni ti won gbagbo lododo ninu yin ati awon eni ti A fun ni mimo ni ipele ipele.'' Q 58:11

Ati pe Olohun tun seni loju oyin ki o maa wa alekun, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَقُلْ رَبِّ زِدْنِي عِلْمًا (114)

''Ki o si wi pe: Oluwa mi, se alekun imo fun mi.'' Q 20:114

Esin Islam gbe ola fun onimimo o si fun ni eto ti o ye bakanna ni o si salaye ipo ti o ni eleyi ni ibamu si oro ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so bayi pe:

ليس من أمتي من لم يجل كبيرنا ويرحم صغيرنا ويعرف لعالمنا حقه

''Ko si lara ijo mi, eni ti ko ba se aponle agbalagba ti o wa ninu wa tabi se ike omode ti o wa ninu wa, ti ko si fun onimimo ti o wa ninu wa ni eto re.'' (Ahmad)

Esin Islam si ka imaa sapa lori wiwa imo ati kiko awon elomiiran si okan ninu awon okunfa ti eniyan fi le ri ogba idera wo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so ninu oro re bayi pe:

من سلك طريقا يطلب فيه علما سلك الله به طريقا من طرق الجنة والملائكة تضع أجنحتها رضا لطالب العلم وإن العالم يستغفر له من في السماوات ومن في الأرض والحيتان في الماء وفضل العالم على العابد كفضل القمر ليلة البدر على سائر الكواكب إن العلماء ورثة الأنبياء إن الأنبياء لم يورثوا دينارا ولا درهما وأورثوا العلم فمن أخذه أخذ بحظ وافر.

''Enikeni ti o ba nrin oju ona kan lati fi wa mimo, Olohun yoo se fun ni okan ninu awon oju ona lati fi wo Al Jannah. Awon Malaika a si maa te iye won sile, ni ti iyonusi, fun eni ti nwa mimo. Ati pe dajudaju awon ti n be ni sanmo ati ile ati awon eja ti o wa ni ibudo yoo maa toro aforijin fun onimimo. Bakan naa ola tin n be fun onimimo lori eni ti n se ijosin da gegebi ola ti n be fun osupa ojo kerinla lori gbogbo awon irawo yoku. Dajudaju awon onimimo ni won jugun awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won), leyi ti o si jepe awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) ko fi owo ponhun tabi owo sile sile, sugbon oun ti won fi sile naa ni imo, enikeni ti o ba ri i mu, onitohun ni o mu ipin ti o tobi (ti o pe).'' (Ibn Hibban).

 

 

 

IPO TI DUKIA (OWO) WA NINU ESIN ISLAM

Esin Islam gba pe gbogbo oun ti nje dukia patapata je oun ini Olohun nikansoso, o si je gbafipamo ati ojuse lodo eni ti o ba wa. Kiko dukia jo gbodo je lati ona ti o to (halal) ni ibamu si ilana ofin Olohun, bakan naa a gbodo naa si awon ona ti o leto ninu ofin Olohun. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

لا تزول قدما عبد يوم القيامة حتى يسأل عن عمره فيما أفناه وعن علمه فيم فعل وعن ماله من أين اكتسبه وفيم أنفقه وعن جسمه فيم أبلاه

''Gigise eru ko ni ye ni ojo ajinde titi won yoo fi bi leere, nipa isemi aye re ibo ni o lo o si, ati nipa imo re ki lo fi se, ati nipa owo re bawo ni o se kojo ati ibo ni o na si, ati nipa ara re nibo ni o gbo si.'' (At tirmidhi)

Esin Islam se ni lojukokoro pe ki a wa a ki a si ko o jo lati fi gbo bukata wa ati awon ti n be labe ikapani wa, ki a si wa iranlowo pelu re lori awon eto isemi aye wa.

Yoo maa je okunfa daadaa fun omoniyan nigbati o ba na an si awon oju ona ti o to. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

المؤمن القوي خير وأحب إلي الله من المؤمن الضعيف وفي كل خير احرص على ما ينفعك واستعن بالله ولا تعجز وإن أصابك شيء فلا تقل لو أني فعلت كان كذا وكذا ولكن قل قدر الله وما شاء فعل فإن لو تفتح عمل الشيطان

''Onigbagbo ododo ti o lagbara, o loore Olohun si feran re ju onigbagbo ododo ti o le (ti o je ole) lo, bi o tile jepe enikookan won loore n be lara re. maa se ojukokoro lori oun ti yoo se o ni anfaani, si maa wa iranlowo Olohun ki o si ma kagara. Ati pe ti nnkankan ba sele si o, ma se maa so pe '' ti o ba sepe mo se bayi ni bayi ni ko ba ri '' sugbon maa so pe '' kadara (ipebubu) Olohun ni eyi, oun ti O ba fe ni yoo se '' nitope gbolohun '' ti o ba sepe'' maa nsilekun ise esu sile (ni).'' (Muslim).

Awon eto miiran (ti o je oranyan) yato si sakah yiyo n be ninu dukia, eyiti o je oranyan lori musulumi ni ki o na dukia re sibi oun ti yoo se ni anfaani laye ati lorun. Olohun ti ola Re ga so pe:

وَابْتَغِ فِيمَا آتَاكَ اللَّهُ الدَّارَ الْآخِرَةَ وَلَا تَنْسَ نَصِيبَكَ مِنَ الدُّنْيَا وَأَحْسِنْ كَمَا أَحْسَنَ اللَّهُ إِلَيْكَ وَلَا تَبْغِ الْفَسَادَ فِي الْأَرْضِ

''Wa ile ikeyin pelu ohun ti Olohun fun o. ma se gbagbe ipin re ni ile aye. Ki o si maa se daadaa gege bi Olohun se se daadaa si iwo naa. Ma se wa ibaje se lori ile. Dajudaju Olohun ko feran awon obileje.'' Q 28:77.

Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

نعم المال الصالح مع الرجل الصالح

''Dansaki owo daradara (owo eto) ti o wa pelu eniyan rere.'' (Ibn Hibbaan).

Esin Islam tako ki a na an ni ina apa, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

وَلَا تُبَذِّرْ تَبْذِيرًا (26) إِنَّ الْمُبَذِّرِينَ كَانُوا إِخْوَانَ الشَّيَاطِينِ وَكَانَ الشَّيْطَانُ لِرَبِّهِ كَفُورًا (27)

''... Ki e si ma se na dukia yin ni ina – apa // e fun ebi ni eto re. (E fun) alaini ati onirin – ajo ti agara da (ni nnkan). Ki e si ma se na dukia yin ni ina – apa.'' Q 17:26-27.

 

 

 

NI IPARI

 Mo gbiyanju lati se oro inu iwe yi ni soki, ki o le je atona ati atoka fun eni ti o ba gbero lati mo nipa esin Islam, pataki ju lo awon ti kii se elesin Islam tele. Eleyi, ki o le maa je ipile fun awon ironu eyi ti yoo maa pese lakaye ati ironu won lati koju ota, eyi ti o ye ki a gbogun ti ki a si wa awon eniyan ni isora lodo re, ati oun ti won lero pe oriire ati aseyori n be nibi ki awon gba tabi lo oun (ibaje) ti won n pepe si.

Nitori naa, mo nso fun iru awon eniyan bayi pe; ki won ma fi lakaye elomiiran ronu, ki won ma si so isemi aye won po mo ife inu elomiiran, Olohun ti ola Re ga nso bayi pe:

وَإِنْ تُطِعْ أَكْثَرَ مَنْ فِي الْأَرْضِ يُضِلُّوكَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ

''Ti o ba tele opolopo awon ti n be lori ile, won maa si o lona nibi esin Olohun.'' Q 6:116.

Nitori pe awon eni ti e ntele loni ni awon eni akoko ti yoo bowo bose kuro lodo yin ni ojo ajinde, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

إِذْ تَبَرَّأَ الَّذِينَ اتُّبِعُوا مِنَ الَّذِينَ اتَّبَعُوا وَرَأَوُا الْعَذَابَ وَتَقَطَّعَتْ بِهِمُ الْأَسْبَابُ (166)

''(Ranti) nigba ti awon ti won tele (ninu aigbagbo) yoo yowo yose kuro ninu oro awon ti won tele won; won ri iya ni. Ohun to si so won po yo si ja.'' Q 2:166.

E gbeyanju lati ni ominira ninu ironu yin, ati lati gbe alamori yewo, ki e si mo ododo yato si iro pelu pe ki e lo oun ti Olohun fun yin ni lakaye. Bakan naa e tun gbiyanju lati la kuro ninu igbarata, eleyameya ti ko wulo ati itele afoju, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:

"وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا إِلَى مَا أَنْزَلَ اللَّهُ وَإِلَى الرَّسُولِ قَالُوا حَسْبُنَا مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ شَيْئًا وَلَا يَهْتَدُونَ (104) ..."

''Nigbati won ba so fun won pe: ”E ma abo wa sibi nnkan ti Olohun sokale. (E ma abo wa) si odo Ojise.” Won a wi pe: ”O Hun ti a baa won baba wa lori re ti to wa.”Se (ohun ti won yoo maa wi niyen), ti o si je pea won baba won ko nimo kan kan, won ko si mona.'' Q 5:104.

Anfaani si wa fun gbogbo eni ti o ba fe, sugbon o gbodo je lati ipase awon ile iroyin tabi mohun maworan ti o se ifonka iroyin ododo nipa esin Islam. Ki a si loo mo pe ki se gbogbo eni ti n pe apemora ije musulumi naa ni musulumi, beeni kii se gbogbo iwe ti won se afiti re si esin Islam naa ni o gbe aworan ododo nipa esin Islam, sugbon a gbodo mu esin Islam lati awon orison re eyi ti o feserinle ti o si je atewogba. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so pe:

افترقت اليهود على إحدى وسبعين فرقة وافترقت النصارى على اثنتين وسبعين فرقة وستفترق أمتي على ثلاث وسبعين فرقة كلها في النار إلا واحدة] قالوا: من هي يا رسول الله؟ قال: ”من كان على مثل ما أنا عليه وأصحابي

''Awon elesin yehudi pin si ona mokanle laadorin (72), awon elesin Nasara (kirisiteni) pin si ona mejile laadorin (72), nigbati ijo elesin Islam naa yoo pin si ona metale laadorin (73), gbogbo won ni yoo wo inu ina ayafi eyokan. Won wa beere wi pe: awon wo ni (eyokan naa) ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)? o si dahun wi pe: enikeni ti o ba wa lori iru oun ti mo wa loni.'' (Ibn Majjah).

Olohun ni O ni mimo ju lo ti O si je Ojogbon ju lo, ike ati ola Olohun ki o ma ba Anabi muhammad ati awon ara ile re ati awon sahabe re.