NJẸ KO TỌ FUN Ọ, KÍ O JẸ MUSULUMI

NJẸ KO TỌ FUN Ọ, KÍ O JẸ MUSULUMI

NJẸ KO TỌ FUN Ọ, KÍ O JẸ MUSULUMI
ألم يأن لك أن تكون مسلما بلغة اليوروبا

 

 

‘Abd Ar-Rahmân bin ‘Abd Al-Karîm Ash-Sheha
د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 


Itumo ni ede Yoruba
EUROPEAN ISLAMIC RESEARCH CENTER (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Abd Ar-Razzaq Isa
Atunto
Ridwanu Allah Murtadho

 
WWW.ISLAMLAND.COM

 

 

NJẸ KO TỌ FUN Ọ, KÍ O JẸ MUSULUMI
Ni orukọ Ọlọhun Ajọkẹ-aiye Àsàkẹ-ọrun.
Gbogbo ọpe ti Ọlọhun nii se, ikẹ ati ọla Ọlọhun ko maa ba Annabi Muhammad, ojiṣẹ Ọlọhun, ati awọn ara-ile rẹ é, ati awọn Saabe rẹ é.
Irẹ oluka alapọnle yii:
Ninu iwe kekere yi, mo gbiyanju lati s’akojo awọn ipin kan ninu awọn iroyin-ẹwa Isilaamu ni ojupọnna ti ó mọ ni iwọnba ki o le jẹ kọkọrọ fun sise iwadi ati iwadi ijinlẹ fun awọn oluwadi nipa ootọ, eleyi ti mo ni igboya lati sọ ‘pe ti awọn onideede enia ninu awọn ti kii se musulumi ba mọ ọ, yio jẹ okunfa wiwọ inu ẹsin Isilaamu pẹlu awọn majẹmu kan, ninu re ni í:
■ Aniyan tootọ lati wa ododo, ati lati mọ ó, ati lati tẹ le e, ti kii se lati se iwadi awon asise, Ọlọhun Ọba ti O mo ti ola Rẹ ga julo ti se adeun fifi eniti o ba ngbiyanju lati mo ododo mọ ọna Rẹ, iyẹn ni latari oun ti yio ma á ri ninu adun, ati isipaya igbaya, ati rirọrun awọn oju-ọna tií mu ni de bẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga julọ sọ pe:
"فَمَن يُرِدِ اللّهُ أَن يَهْدِيَهُ يَشْرَحْ صَدْرَهُ لِلإِسْلاَمِ وَمَن يُرِدْ أَن يُضِلَّهُ يَجْعَلْ صَدْرَهُ ضَيِّقاً حَرَجاً كَأَنَّمَا يَصَّعَّدُ فِي السَّمَاء كَذَلِكَ يَجْعَلُ اللّهُ الرِّجْسَ عَلَى الَّذِينَ لاَ يُؤْمِنُونَ "
" eniti Ọlọhun ba fẹ fi ọna mọ yio si igbaya re fun Islam, eniti O ba fe fi sile ninu isina yio se igbaya re ni hiha (funfun) gadigadi bi (igbaya) eniti gunke losi sanma. Bayi ni Ọlọhun se ẹgbin (iwa) fun awon eniti ko Gbagbọ." Suratu Al-An'am:125.
■ Sise adua tootọ si ọdọ Ọlọhun nikan, ati didunni mọ ọ, lati mọ ododo ati ṣiṣe kongẹ gbigba odo Rẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga julọ sọ bayi pe:
"كَانَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً فَبَعَثَ اللّهُ النَّبِيِّينَ مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ وَأَنزَلَ مَعَهُمُ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ لِيَحْكُمَ بَيْنَ النَّاسِ فِيمَا اخْتَلَفُواْ فِيهِ وَمَا اخْتَلَفَ فِيهِ إِلاَّ الَّذِينَ أُوتُوهُ مِن بَعْدِ مَا جَاءتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ بَغْياً بَيْنَهُمْ فَهَدَى اللّهُ الَّذِينَ آمَنُواْ لِمَا اخْتَلَفُواْ فِيهِ مِنَ الْحَقِّ بِإِذْنِهِ وَاللّهُ يَهْدِي مَن يَشَاءُ إِلَى صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ "
" Gbogbo awọn eniyan jẹ iran kanṣoṣo; Ọlọhun gbe awọn Annabi dide ni Olufunni ni iro idunu ati olukilo atipe O un si sokale fun won, tira na pelu ododo ki O ba se idajo larin awon eniyan nipa ohun ti won se iyapa enu si, ayafi awon ti A ti fi fun leyin ti ododo ti wa ba wọn niti ilara larin ara won. Ọlọhun tọ awọn ti o Gbagbọ si ọna nipa ohun ti wọn se iyapa ẹnu si ni ti ododo pẹlu asẹ Rẹ, Ọlọhun A ma fi ẹni ti O ba fe mọ ọna ti o se tara (ona ti o tọ tii se ona esin Isilaamu). Suratu Bakorah:213.
■ Gbigbe ise ẹyamẹya ẹsin ati itẹle afọju jusile nibi ẹsin awọn baba ati awọn baba baba, eyiti o duro lori aimọkan ti o jina si ododo ati imọ, ati mimọ ka awon iwe lati mọ nipa ẹsin Isilaamu pẹlu ọpọlọ ati imọ lasan ti o jina si igbarata esin ati mima tẹle awọn irori ajogunba. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga julọ ṣọ bayi pe:
"وإذا قيل لهم اتبعوا ما أنزل الله قالوا بل نتبع ما ألفينا عليه آباءنا أو لو كان آباؤهم لايعقلون شيئاً ولا يهتدون"
" Nigbati a ba sọ fun pe: Ẹ tẹle ohun ti Ọlọhun sọ, wọn a wipe: Bẹẹkọ! awa ntẹle ohun ti a ba lọwọ awọn baba wa. Njẹ ki wa sepe awọn baba wọn ko ni oye kan, wọn ko si ni itọṣọna." Suratu Bakọrah:170.
O wa didandan fun oluwa’mọ ninu awọn ti kii se musulumi pe ẹsin isilaamu ko si fun awọn larubawa, bi kii se pe o wa fun gbogbo agbanla-aye lapaapọ, ko si ẹyamẹya ninu Isilaamu. Ẹniti o ba ni igbagbọ si i ti o si tẹ le e, iru eniyi ni musulumi, koda ko se pe o wa ninu awọn ti ilu wọn jina ju, dudu lo jẹ ni tabi funfun, eniti o ba te le é, ti ko si ni igbagbọ pẹlu rẹ kii se musulumi koda ko se pe ninu ara iran Annabi isilaamu ti se Muhammad -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ma ba á- ni o ti wa. Bilal ọmọ Rabah – ki Olohun o yọnu si í- oluperun ojisẹ Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ma ba á- jẹ ẹru lati ilẹ Habasha (Ethopia) , ti Suhaybu si jẹ ara ilẹ Roomu, ti Salman si jẹ ara Farisi, bakanna lo se pe ẹsin isilaamu ko mọ lori ilu Makkah ati madinah ati orisun ile larubawa nikan, bi kii se pe gbogbo ilu ti ba ntẹ le ẹsin isilaamu ni ilu musulumi koda ko se pe o jẹ ilu aginju lati ilẹ afirika (alawọ dudu).
■ Gbigba ẹsin Isilaamu ati sise idajo le lori gẹgẹbi ọna ati ofin t’ope, kii se pe gbigba ẹsin Isilaamu ati sise idajo le lori pẹlu awon isesi awon eniyan kan tabi ilu kan ti ko si nipo eniti a le bi lere, atipe o mbẹ ninu ọpọlọpọ awọn ikọ ati awọn ilu ti nfi ara wọn ti si Isilaamu to si jẹ pe Isilaamu bọpa-bọsẹ kuro ni ọdọ wọn, ti eyi si ni ilapa topọ nibi fifi abuku kan ẹsin Isilaamu tootọ ati nibi lile awọn ti kii se musulumi jina si í, ati kikọ fun wọn nibi gbigba ẹsin Isilaamu na latara awọn isesi ati awọn adiọkan ati awọn ihuwasi yala l’ọrọ ṣiṣọ ni tabi ni iṣe ti wọn nse ti lakayi ti o ni alafia yoo kọ ọ, ti adamọ ati awujo ọlaju yio si kọ ọ, nibi awọn ohun ti wọn fi nti si ara ẹsin Isilaamu. Nigbana, ki o di mimọ fun wa pe gbogbo adiọkan kan tabi iṣeṣi kan ti o ba tako adamọ todara ati lakaye ti o ni alafia, ti awọn ẹyá ara idankan-mọ ti o pe ju si kọ ó, ti awọn musulumi o si f’ẹnu ko le lori kií se lara ẹsin isilaamu rara nitoripe Isilaamu ẹsin ọkanṣoṣo, ni ẹbọ sise koropọ mọ ọ, ati ijọsin ti sekarimi ko dapọ mọ ọ, ati iwa daada ti iwa iyẹpẹrẹ ko si lara rẹ, ati ofin idari isemi aye ti kosi aaye ninu rẹ, ti o si han gbangba ti kosi afipamọ ninu rẹ, sugbọn awọn musulumi jẹ oniran-n-ran nibi gbigbamu ati nibi titẹle larin ẹniti o samojuto kekere ati alamojuto pupọ ninu awọn nkan yii. Ọlọhun ti s’alaye eleyi ninu Alukur'anu pẹlu ọrọ Rẹ bayi pe:
"ثُمَّ أَوْرَثْنَا الْكِتَابَ الَّذِينَ اصْطَفَيْنَا مِنْ عِبَادِنَا فَمِنْهُمْ ظَالِمٌ لِنَفْسِهِ وَمِنْهُمْ مُقْتَصِدٌ وَمِنْهُمْ سَابِقٌ بِالْخَيْرَاتِ بِإِذْنِ اللَّهِ ذَلِكَ هُوَ الْفَضْلُ الْكَبِيرُ "
" Lẹyinna A jẹ Tira na logun fun awọn eniti A sa lẹsa ninu awon erusin Wa; nbẹ ninu won eniti o je alabosi fun ori ara re, oluse dede wa ninu won, oluse yarayara si (ise) rere wa ninu won pelu iyọnda Ọlọhun, eyi si ni ore ajulo ti o tobi." Suratu Faatir:32
■ Gbigba imọ nipa esin Isilaamu latara sise iwadi gidi, laise latara awon ohun igbohun si afẹfẹ ti won kii se ohun-deede, abi awon eniyan ati awon okunfa ti won jẹ ọta fun esin isilaamu. Nitorina o jẹ dandan fun eniti o ba fẹ mọ nipa Isilaamu ki o gba imo nipa re lati inu awon ipilẹ rẹ to ni alafia ti se Al-Qur'ani ati ilana Anabi to fi ẹsẹ rinlẹ, leyinna afẹnuko ijọ musulumi. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Olohun maa ba á- sope:
" mo fi nkan meji sile fun yin; e ko ni sọnu nikugba ti e ba ti dimọ ọ awon mejeji (awon naa ni) tira Ọlọhun ati ilana mii." Al-Baani sope: Hadisi to dara ni.
■ Gbogbo eniyan ni o ma nwa ohun ti o dara julọ ti o si pe julo nibi gbogbo alamori rẹ ti ile-aye. Eleyi jẹ adamo fun omo eniyan ti Ọlọhun da omo eniyan le lori, eleyi yoo waye larin mimu ohun ti o se deede ti o si dara julọ latara sise afiwe larin awon ohun ti mbẹ ni waju rẹ, bakanna ni idakeji, ni o jẹ pe wọn nfẹ ni odọ rẹ ki o se iwadi nipa esin ti o dara julo ti o si pe julo eyiti yoo je ki o se orire ti yio mu lati ni ifokanbale ẹmi ati Alafia-ara ati lakaye ati ijẹ ọmọluabi re ati dukia rẹ, eleyi ko le ribẹ ayafi latara kika pelu ifarabale ati isafiwe tòdodò, ati aimọkanju nibi sise idajo ati sise suru nibi sise idajo koda ko se pe idajo na wa labẹ ikapa re.
■ Ki a lo mọ amọdaju pe alamori na je ti ibuseri si, agbèrò pelu eleyi; isẹmi leyin iku eyi ti o se pe yala ninu ki o ja si ogba idera (Alujannah) ti o se pe ibu re da gẹgebi ibu sanma ati ile, abi ki o ja si inu ina to njo fofo to sepe omo eniyan ati okuta ni won yoo fi ko ó, ti awon malaika ti won ni ipa ati agabara jẹ olusọ rẹ ẹ, ti won ki si yapa asẹ ti Ọlọhun ba pa won, wọn si ma nse ohun ti O ba pa won lase. Ọlọhun ti ola Rẹ ga julo so pe:
" وَكَذَلِكَ أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ قُرْآناً عَرَبِيّاً لِّتُنذِرَ أُمَّ الْقُرَى وَمَنْ حَوْلَهَا وَتُنذِرَ يَوْمَ الْجَمْعِ لَا رَيْبَ فِيهِ فَرِيقٌ فِي الْجَنَّةِ وَفَرِيقٌ فِي السَّعِيرِ "
“ Bayi ni A fi Al-Kurani ranse si ọ ni ede larubawa, ki o le ma fi se ikilọ fun iya-ilu na ati awon ti o wa ni agbegbe re, ki o si ma se ikilo nipa ojo akojọ, ti ko si iyemeji ninu re. Awon ijo kan yoo wa ni alijanna (ogba idera) ti awon ijo kan yoo wa ninu ina to njo." Suratu Shura:7.
Mo mbẹ Ọlọhun fun gbogbo eniti o ba ka iwe yi pe ki o fi won se kongẹ (anu Re), ki O si f’ẹse won mulẹ (lori ododo), ki O si sipaya igbaya won fun gbigba ododo ati tite le é.


kini njẹ Isilaamu?

Isilaamu ni ijuwọ-jusẹ sile fun Ọlọhun, eleyi ti o ri bi Ọlọhun (ti O mọ ti ola Re si ga julo) se fẹ l’ọdo re, ki o mọ se ijosin fun Oun nikan, ki o si ma mu orogun pelu Re, ki o si maa tẹ le awon aṣe Re, ki o si jina si awon ohun ti O kọ. Isilaamu ni ajosepọ lailai larin musulumi ati Oluwa re, o ma npe lẹmarun lojumo nibi kiki awon irun eleyi ti O (Ọlọhun) se lọranyan le lori ki a to wa sọ nipa awon asegbọọrẹ (nafilah asegbọọrẹ), gẹgebi o se jepe yoo ma ni itẹsiwaju ajosepo pelu Oluwa rẹ latara awon adua ati awon iranti (Ọlọhun) eleyi ti yoo mo dunnimọ sise won nigbati o ba nse awon ise oojọ rẹ eleyi ti yoo ma se alekun ajosepọ re pelu Rẹ (Oluwa). Awon adua (asikiri) kan wa saaju ounjẹ jijẹ ati lẹyin ti a ba jẹun tan, ati adua (asikiri) ti a ba fẹ wo ile-ẹgbin ati ti a ba jade lati’bẹ, ati adua (asikiri) ti a ba fe wo inu-ile ati ti a ba fe jade, ati adua (asikiri) nigbati a ba fe sun ati adua (asikiri) nigbati a ba ji (latoju orun), ati adua (asikiri) aluwala sise ati nigbati a ba pari’ẹ, ati asikiri eyi ti o wa fun nigbati ọkọ ati aya ba fẹ ni ajọsepọ tọkọ-taya, ati adua (asikiri) gigun nkan gun, ati bẹẹbẹlọ.. gbogbo isẹmi-aye musulumi wa fun ijosin fun Ọlọhun ati isunni mọ ọ. Ọlọhun ti ọla Re ga julo so bayi pe:
"قُلْ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ "
" Wipe: Dajudaju irun mi ati pipa eran se esin mi ati igbesi aiye mi ati pipapoda mi fun Ọlọhun ni, Oluwa gbogbo eda." Suratu Ahl-Imran:162.

Ninu awon Iroyin (aladani) fun Isilaamu

Botijẹpe esin Isilaamu ni opin awon ẹsin sanma niti sisọkale, ohun ni ẹsin kanṣoṣo eyiti Ọlọhun ko yọnu si ki a sin pelu rẹ ẹsin miran ti o yato si, gẹgẹbi O ti salaye pelu oro Rẹ pe:
"وَمَنْ يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَنْ يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ "
" Enikẹni ti o ba tun wa esin kan yato si Isilaamu, A ko ni gba a lọwo re, yoo si wa ninu awon eni-ofo ni ojo ikẹhin." Ahl-Imran:85.
O pan dandan ki esin na o ni awon iroyin aladani ti yio se opinya rẹ ti yoo si je ki o je esin ti yio ba gbogbo igba ati gbogbo aaye mu titi di ojo ikehin. Ninu awon iroyin na ni:

1 . Adamọ:
Isilaami jẹ esin adamọ ti o ni alafia ti Ọlọhun da omo eniyan le lori eleyi ti won mọ lori adiọkan bibẹ Ọlọhun, ti yoo mọ Ọlọhun pẹlu rẹ latara rironu si idera Ọlọhun ati rironu si agbanl-aiye yi ti O (Ọlọhun) mu wa sinu re. Ọlọhun ti ola Re ga julo sọ pe:
"فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفاً فِطْرَةَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللَّهِ ذَلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ "
" Nitorina da oju rẹ kọ ẹsin ododo, ni eniti o gunri si í, ti o si duro deede lori re, adamo Ọlọhun eyi ti O da omo eniyan le lori, kosi iyipada ninu adamo Ọlọhun, eyi ni esin ti o duro deede, sugbọn opọlopọ awon eniyan ko mọ." Suratu Ruum:30.
Eleyi ni ipile nibi dida eda lapapọ, sugbọn oseese ki awon nkan ti orokirika adamọ yi lapa lara re lọdọ ọmọ-eniyan, ti yoo wa yipada ti yoo si mu kuro loju re to lalafia ti yoo wa sonu kuro nibẹ, yoo wa ma dorogun pelu Ọlọhun, tabi ki o ma sin nkan miran pelu Re, tabi ki o kọ bibẹ RE (Olohun). Ojisẹ Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe:
" won kii bi omo Kankan ayafi ki won bi lori adamo (ẹsin Ọlọhun), sugbon awon obi rẹ ni won yoo sọ ọ di yahudi, tabi nasara tabi olubọ-ina." Bukhori ati muslim logba wa

2 . Okanṣoṣo:
Isilaamu ni esin ise Ọlọhun l’ọkan ati ise afọmọ (ijosin) eleyi ti npase sinsin rẹ fun Ọlọhun nikan soṣo ati sise É l’aaso nibi ijosin laimu orogun pelu re. O fi ajọsepọ ti koni alagata ninu lelẹ -pelu eleyi- larin Ọlọhun ati awon eru Re eyiti o wa lori igbagbo pelu Re ati siserilọ si ọdo Re fun gbigbọ awon bukata ati wiwa aforijin (ẹsẹ) ati iranlowo l’ọdo Re laimu alagata pẹlu’ẹ. O p’aná mimu awon alagata larin Ọlọhun ati awon erusin Re, o si fi enu ate lu awon ọsẹbọ l’ori mimu awon alagata nibi ijosin. Ọlọhun ti ola Re ga julo nfun wa niro nipa won pe:
"أَلَا لِلَّهِ الدِّينُ الْخَالِصُ وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللَّهِ زُلْفَى"
" Jẹki nsọ fun ẹ, ti Ọlọhun ni esin ti o mọ, atipe awon eniti won nmu alafeyinti leyin Ọlọhun (won yoo ma sọ pe): a wa ko sin won bikose pe ki won le sun wa mọ Ọlọhun ni pẹkipẹki…" Suratu Zumar:3.
Itumo Gbolohun taoheed (ise Ọlọhun l’ọkan)" La ilaha illa-Lahu" nipe: kosi eniti ijosin to si ni ododo leyin Ọlọhun (Allahu), Oun ni kọkọrọ wiwọ inu Isilaamu nitori rẹ ni Ọlọhun fi da ẹda ati alujanna (ọgba idera) ati ina, ohun ni ipepe gbogbo awon ojise ati awon Annabi -ki alafia o maa ba won- l’atori Nuhu titi de ori opin won Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-. Ọlọhun ti ola Re ga julo sọ pe:
" وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ مِنْ رَسُولٍ إِلَّا نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدُونِ "
“ Awa ko ran ojise kan nisẹ siwaju rẹ ayafi ki A ranse si í pe dajudaju ko si Ọlọhun kan ayafi Emi, nitorina ki e ma sin Mi." Suratu Al-Ambiyai:25.

Gbolohun taoheedi ntumọ si:
■ Mimu Ọlọhun l’ọkan nibi ijọsin fun u, eleyi tii se kikọ gbogbo ijosin fun nkankan l’ẹyin Re ati fifi won (awon ijosin) rinlẹ Fun u nikan ati sise ni aso ninu ijosin, a ko ni mu orogun kankan pelu Re nibi ijosin Re. Olohun so bayi pe:
" ذَلِكُمُ اللّهُ رَبُّكُمْ لا إِلَـهَ إِلاَّ هُوَ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ فَاعْبُدُوهُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ "
" Ọlọhun yi ni Oluwa yin, kosi Ọlọhun miran afi Oun na, Ẹlẹda gbogbo nkan, nitorina ẹ sin I, on si ni Olusọ lori gbogbo nkan" Suratu Al-An'am:102.
■ Sise Ọlọhun l’ọkan nibi sisẹda, eleyi ni adiọkan pe Oun ni Oluwa gbogbo nkan ati Oludari rẹ, Oluda-eda ati Olupese (ije-imu) fun won, Olumuwon semi Olupawon, ati Olugbewon dide l’ọjo ti kosi iyemeji ninu re. Ko si oluseda Kankan, abi olukapa Kankan abi oludari Kankan ninu agbanla-aiye yi ayafi Ọlọhun, kosi olupasẹ ijọsin ati oluseto tita-rira fun awon omo eniyan kookan abi awon ijọ, kosi olusọ nkan di ẹto tabi olusọ ọ di eewo ayafi Ọlọhun. Ọlọhun so bayi pe:
"هُوَ الْحَيُّ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ فَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ"
" Oun ni Alaaye, ko si Ọlọhun miran ayafi Oun, nitorina ẹ ma ke pe E niti eniti o un se afọmọ ẹsin fun U. Opẹ ni fun Ọlọhun Oluwa gbogbo ẹda." Suratu Gọọfir:65.
■ Sise Olohun ni aaso nibi awon oruko Re ati awon iroyin Re. Oun ni ije eyọkan Re nibi gbogbo awon iroyin t’ope eleyi totumọ si sise afọmo Re kuro nibi gbogbo alebu ati adinku, ati kuro nibi gbogbo afijọ ati afiwe. Ọlọhun ti O ga julọ so bayi pe:
فَاطِرُ السّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ جَعَلَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجاً وَمِنَ الْأَنْعَامِ أَزْوَاجاً يَذْرَؤُكُمْ فِيهِ لَيْسَ كَمِثْلِهِ شَيْءٌ وَهُوَ السَّمِيعُ البَصِيرُ"
“ Olupileda sanma ati ilẹ. O si se yin ni takọ-tabo lati inu ara yin, awon eran na O se won lakọ-labo, O se eda yin sibe. Kosi kinikan ti o dabi Re; (Ọlọhun) Oun ni Olugbọrọ, Oluriran ”. ashuro 11.

3 . Sise ijọsin:
Ọlọhun ko da ọmo-eniyan ayafi nitori ijosin fun U, gẹgẹbi Ọlọhun ti fun wa niro pelu ọro Re pe:
"وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنْسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ "
" Atipe mi O seda alijannu ati ọmo-eniyan ayafi ki wọn le maa se ijosin fun Mi." Suratu Dhariyaat:56.
Bukata omo eniyan si ijosin jẹ bukata adamọ, gẹgebi o se jẹ pe ara omo eniyan se ni bukata si jijẹ ati mimu ki o le ma sẹmi bẹẹ naani ẹmin wọn ni bukata si ijosin nitori ki o le baa ni ifọkanbalẹ. A o ri eleyi kedere l’ọdo gbogbo ọmo eniyan laisi ayafi kankan, won ma nsẹri awon bukata won lọ si ọdọ Olujọsin fun u, won si ma nni igbọnmọ ifọkanbalẹ ẹmi nibi gbigbe ara le E. Gbogbo awọn ọmọ eniyan wa lori imaajosin fun Ọlọhun ọkanṣoṣo lati ori Annabi Adam (ki alafia o maa ba á) titi di asiko annabi Nuhu (ki alafia o ma ba á), sugbọn ẹbọ sise pẹlu Ọlọhun s’ẹlẹ l’ori awon ijọ re (Nuhu), won wa nsin oriṣa. Eleyi ni ibẹrẹ iran ẹbo sise ti o wa di oniranran, a wa ri ninu won ti nbọ okuta, tabi igi ati awon ẹranko, tabi awon nkan miran, bayi ni Ọlọhun se ran awon ojisẹ lati da won pada si ibi adiokan t’omọ pọnrangandan ati ijọsin ti o la kuro nibi ẹbo. Koda awon eniti won gunri kuro nibi bibẹ Ọlọhun ti won koni igbagbo pe Ọlọhun mbẹ -ki Ọlọhun O sọ wa kuro nibẹ- ni ohun ti awon na nsin, toripe oun sin ifenu re ati esu re ati ohun ti emin rẹ nfẹ. Eleyi jẹ opin abosi si emin ara ẹni ati si ẹlomiran nitoripe o ngbe ile-aye yi laini asunta ẹmin ati ninu wahala ẹmin ti ina to njo fofo ti enikankan koni wo inu re ayafi oloribu ti o pe ọro Ọlọhun ni’rọ, ti o si gunri yoo si je ti ẹni ohun ati abosi rẹ si elomiran nitoripe yoo ma se ohun ti o ba ifẹ ati erongba inu rẹ mu, koda kosepe yoo pa elomiran lara, koni si ipilẹ kankan ti yoo se aponle rẹ tabi adiọkan kan ti yoo pa asẹ rẹ mọ nibi ohun ti o ba se l’ẹtọ abi ti o kọ. Eleyi nibamu si ọro Ọlọhun ti ola Re ga julo to sọ pe:
" أَفَرَأَيْتَ مَنِ اتَّخَذَ إِلَهَهُ هَوَاهُ وَأَضَلَّهُ اللَّهُ عَلَى عِلْمٍ وَخَتَمَ عَلَى سَمْعِهِ وَقَلْبِهِ وَجَعَلَ عَلَى بَصَرِهِ غِشَاوَةً فَمَن يَهْدِيهِ مِن بَعْدِ اللَّهِ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ "
" Njẹ irẹ ri eniti o fi afẹẹnu rẹ sin Ọlọhun rẹ, Ọlọhun si mọọmọ fi i sile ninu isina, atipe Ọlọhun fi odidi di eti re ati ọkan re, O si fi ebibo bo oju re? Tani eniti yoo fi ona mọ ọ l’ẹyin Olohun? Enyin ko ronu ni? ” Suratu Jathiyah:23.
Ni agbaye lapapọ, ti o ba wo ẹgbe rẹ, iwọ yoo ri eniti on dorogun pẹlu Ọlọhun, oó ri eniti o nsin ẹlomiran leyin Ọlọhun ayafi awon musulumi ti won jẹ aladiọkan to dara, ti won fi ara won sile fun Ọlọhun nikansoso ti koni orogun. Awon yahudi yi (ọrọ Ọlọhun) sodi, won pe Uzayru ni ọmo Ọlọhun, awon nasara yi (ọro Ọlọhun pada) won pe messiah ni ọmo Ọlọhun, ki wa ni a o sọ nipa awon eniyan yoku ti won nsin awon nkan miran gẹgebi orisa, tabi ẹranko, tabi irawo ti lakai t’odara t’osi pe, ati adamọ ti o ni alafia yoo si kọ ọ, ti ọkan ti o dara yoo si tako ó. Ọlọhun nsọ ododo nigbati O sọ pe:
إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ عِبَادٌ أَمْثَالُكُمْ فَادْعُوهُمْ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ "
" Dajudaju awon ẹniti ẹ npe lẹyin Ọlọhun jẹ ẹru bi ẹyin na; ẹ pe won, ki awon si da yin l’ohun bi e ba je olododo." Suratu A'raf:194.

4 . Sise apọnle lakai:
Isilaamu jẹ ẹsin to se apọnle lakai ati ironu, opolopo awon itọka lati inu Al-qur'ani lo npepe si imaalo lakai, o si nse loju-ẹyin si imaase lakai ati imaa-ronu jinlẹ, " njẹ won ó wa se lakai ni ?, "se won ó wa ronu ni bi ?", "se won ó wa mọ ni ?", "se won ó wa woye ni ?". Ọlọhun ti ola Re ga julo sọ pe:
" إِنَّ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِلْمُؤْمِنِينَ (3) وَفِي خَلْقِكُمْ وَمَا يَبُثُّ مِنْ دَابَّةٍ آيَاتٌ لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ (4) وَاخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَمَا أَنْزَلَ اللَّهُ مِنَ السَّمَاءِ مِنْ رِزْقٍ فَأَحْيَا بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا وَتَصْرِيفِ الرِّيَاحِ آيَاتٌ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (5) " الجاثية (3-5)
" Dajudaju ninu sanma ati ile ami nbe fun awon onigbagbo ododo * Ati ninu dida yin ati awon eda ti O tan kakiri (orile) je awon ami kan fun awon enia ti won mọ amọdaju.* Ati yiyapa sira won oru ati ọsan ati ohun ti Ọlọhun sọkale lati sanma ni ipese, ti O si fi ji ile leyin ti o ti ku ati yiyipada awon atẹgun jẹ awon ami fun awon eniyan ti won ni lakai." Suratu Al-Jathiyah:3-5.
Sugbon o se agbekalẹ awon aye lilo lakai ati ironu, ohun-na ni ki o je nibi awon nkan ti o ni anfani, ti o si se lepa-ba pelu awon ohun igbonmọ gẹgebi igbonmọ igbọrọ ati iriran ati awon omiran. Sugbon kosi aaye fun lilo lakai nibi awon alamori ikọkọ ti a ko le lepa won pelu awon ohun igbonmọ, toripe lilo lakai nibi awon nkan wonyi je fifi igbiyanju ati agbara sofo nibi ohun ti kole mu anfani kankan wa. Omo eniyan kole ni mo nipa kọkọ ayafi lati ọdo awon ojise eleyi ti Ọlọhun ran won nise. Ọlọhun ti ola Re ga julo sọ bai pe:
"عَالِمُ الْغَيْبِ فَلَا يُظْهِرُ عَلَى غَيْبِهِ أَحَداً إِلَّا مَنِ ارْتَضَى مِن رَّسُولٍ فَإِنَّهُ يَسْلُكُ مِن بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ رَصَداً"
" O ni imọ ohun ti o pamọ, nitorina kii fi ohun ti o wa ni ipamo Re han enikankan." * Ayafi eniti O ba yọnu si ni ojisẹ kan, Yio je ki olusọ kọọkan ma be ni iwaju rẹ ati eyin re." Suratu Al-Jinn:26-27.
Gbogbo awọn ilana ẹko Isilaamu lo njẹri si ododo ati anfani awon lakai to dara ati awon ironu gidi onidede fun awon omo eniyan, gbogbo awon aṣẹ rẹ ati awon ohun ti o ba ko ni o je deede ti ko si abosi ninu re, ko ni pa ase nkankan ayafi ki o je anfani patapata, abi anfani ti o gbe won, kosi ni ko nkankan ayafi ki o je anfani patapata, abi ki aburu rẹ ju ore inu rẹ lọ, eleyi ko pamọ fun eniti o ba ronu si awon itoka (aya) inu Al-qur'ani ati awon Hadith ojisẹ Ọlọhun ti won ni alafia.

5 . O jẹ esin lati ọdọ Ọlọhun:
Awon ilana ẹkọ Isilaamu wa lati odo Ọlọhun nibi gbogbo ohun ti o ni se pelu adiọkan, ijosin, iwa, ati awon eto. Awon nkan wonyi je ohun ti o fẹse mulẹ ti won kosi gba iyipapa abi fifi nkan miran dipo won. Ọlọhun ti ola re ga julo so pe:
"تَنْزِيلٌ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ "
" Nkan ti ó sọkale ni lati ọdo Oluwa gbogbo ẹda." Suratu Al-Wakia:80.
Kii se agbelẹrọ omo-eniyan ti adinku ati asise ati ilapa pelu awon ohun ti o rokirika won le sẹle si won. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
"أَفَحُكْمَ الْجَاهِلِيَّةِ يَبْغُونَ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ حُكْمًا لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ"
" Nje idajo igba aimokan ni won nwa bi? Tani eniti o dara ju Ọlọhun lọ ni idajo fun awon eniyan ti o mọ amọdaju." Suratu Al-Maida:50.
Isilaamu jẹ esin kansoso ti ayipada ati pasiparo ko wo inu re, awon itoka re la kuro nibi adinku, ati alekun. Awon ohun ipile ofin Isilaamu (sharia ti Isilaamu) ni:
a . Al-Qur'an-l-Kareem: Al-Qur'an wa gegebi o se wa lati igba ti won ti sọ ọ kalẹ fun Anabi Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- pelu awon arafi re ati awon aaya re (itọka rẹ), ati awon sura re titi di asiko wa yi, ti iyipada kankan, abi alekun kankan, abi adinku kankan ko wo inu re, ti awon onka topọ gba a wa lati ọdo awon onka topọ latara kikọ ọ sinu iwe, ati hiha wọn si agbari, tosepe korọrun ki wọn fi ẹnu ko lori iro. Nipaapa awon Musulumi se ojukokoro to lagbara lori Al-qur'an, nitorina won ma nsare tete losi bi kikọ rẹ ati ikọ-ni rẹ ni erogba lati ri oore ti ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so nipa re pelu ọro rẹ to so pe:
“eniti o dara ju ninu yin ni eniti ó kọ Al-qur'an ti o si fi nkọ ni." Al bukhori
Ati nitoripe o jẹ ohun ti a fi ma nse ijosin pelu hiha rẹ ati kika rẹ fun Ọlọhun. Ojisẹ Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe:
" enikeni ti o ba ka arafi kan ninu Tira Ọlọhun yio gba ẹsan (daada) kan lori rẹ, ti daada kan sise deede ilọpo mẹwa iru re, mi o sope (Alif lam mim) jẹ arafi kan, sugbon Alif je arafi kan, Lam je arafi kan, Mim je arafi kan." Tirmidhi.
b . Sunnah alapọnle ti ojise Ọlọhun ni ipilẹ elekeji fun ise idajo ti o si je alaye fun Al-qur'an alaponle, alaye si opọlopo awon idajọ re. Ó la kuro nibi ki aburu abi agbelẹrọ ati irọ wo inu re latara ipasẹ awon eniyan olododo onideede ti won na ara won ati isemi won lati ko awon Hadith ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ati lati kọ awon okunfa ẹgbawa won, ati ipo won nibi nini alafia ati lilẹ, ati nipa awon eniti won gba won wa, ati ipo won nibi rere ati aburu, won mọ gbogbo Hadisi eleyi ti won gba wa lati ọdo ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- won ko fi ikankan rinlẹ ayafi eleyi ti o ba fese rinlẹ lati odo ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-, bayi ni won se de ọwọ wa ni eyi ti ó mọ, ti ó si la kuro nibi awon Hadisi eleyi ti won jẹ irọ.

6 . Agbaye:
Isilaamu ni esin agbaye ti a ran si gbogbo eniyan lapapọ, funfun ni, dudu ni, larubawa ni, tabi eniti ki se larubawa, ni gbogbo asiko ati aye laisi ayafi. Ohun ni esin ti gbogbo eniyan ri bakankan-na ninu rẹ lori adiokan ti o mọ ti ó rinle ti o ko won jọ, ti kii se lori ipilẹ awọ, tabi ede, tabi ileto, tabi iran, tabi asiko, tabi aye, gbogbo eniti o ba ni igbagbọ pe Ọlọhun ni Oluwa, atipe Isilaamu ni esin ododo, atipe Anabi Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- je ojise, ni yoo wọle si abẹ iboji Isilaamu ni eyikeyi asiko ati eyikeyi aye. Sugbon eyi to yato si (Isilaamu) ninu awon esin torekọja je esin ti won doju ọro inu re ko awon ijo kan ti a se adayanri won ni asiko kan ti a se adayanri re, ti awon ofin ati awon idajo inu re si je adayanri fun won ni asiko won ti ko si le tataporo bọ si ọdo awon miran, koda bosepe won papọ pelu’ẹ (Islam) nibi ipilẹ esin. Annabi Musa -ki ike ati alafia maa ba á- je eniti won ko ran nise ayafi si awon ọmo Isirẹli nikan. Ọlọhun ti ola Re ga julọ sọ bayi pe:
 "وَآتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَجَعَلْنَاهُ هُدًى لِّبَنِي إِسْرَائِيلَ أَلاَّ تَتَّخِذُواْ مِن دُونِي وَكِيلاً "
" Atipe Awa fun Musa ni Tira, Awa si se é ni afinimọna fun awon omo Isirẹli pe: ẹ ko gbọdo mu olufarati kan leyin Mi." Suratu Isra':2.
Nigbati igba ti rekọja lori awon ọmo Isirẹli leyin Anabi Musa -ki alafia maa ba á- won gunri kuro nibi ilana Ọlọhun ti Anabi Musa -ki alafia maa ba á- se alaye re fun won, nitorina won sonu kuro nibi ona-ododo, nigbana Ọlọhun ran Anabi Isa -ki alafia maa ba á- si won, ki o le da won pada, ki o si le to won si oju ona ododo. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
"وَقَفَّيْنَا عَلَى آثَارِهِم بِعَيسَى ابْنِ مَرْيَمَ مُصَدِّقاً لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ وَآتَيْنَاهُ للْمُتَّقِينَ "
“Atipe Awa fi Annabi Isa ọmo Mariyama tẹle ipase won, ti o je ki a mọ ododo nipa ohun ti o ti siwaju re ninu At-taorata; A si fun u ni Injila; imọna mbẹ ninu re ati imole ti o je ki a mo nipa ohun ti o ti siwaju re ninu At-taorata, o si je imona ati isiti fun awon oluberu” (Ọlọhun). Suratu Maida:46.
Leyin asiko die ti awon ojise ti rekoja, Olohun gbe Annabi Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- dide, O si ran si awon awujọ meji na (omo eniyan ati alijannu) lapapo, O si fi se opin awon iranse. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
" تَبَارَكَ الَّذِي نَزَّلَ الْفُرْقَانَ عَلَى عَبْدِهِ لِيَكُونَ لِلْعَالَمِينَ نَذِيراً "
" Ibukun ni fun Eniti O sọ Olupinya ododo kuro ni ara iro ka’lẹ fun ẹrusin Re ki o le ba je olukilo fun gbogbo eda." Suratul-Furkon:1.
Pelu bosejẹ esin agbaye, kii jẹ eniyan nipa lati wọ inu re, bikiisepe o fi aye ominira sise asanya gbigba á, tabi kikọ ó silẹ fun eniti o ba de etigbọ re, sugbon o se alaye ibuseri si eniti o gunri kuro nibi titele é. Ọlọhun ti ola Re ga julo sope:
"وَقُلِ الْحَقُّ مِن رَّبِّكُمْ فَمَن شَاء فَلْيُؤْمِن وَمَن شَاء فَلْيَكْفُرْ إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلظَّالِمِينَ نَاراً أَحَاطَ بِهِمْ سُرَادِقُهَا وَإِن يَسْتَغِيثُوا يُغَاثُوا بِمَاء كَالْمُهْلِ يَشْوِي الْوُجُوهَ بِئْسَ الشَّرَابُ وَسَاءتْ مُرْتَفَقاً "
" Wipe: Otito lati ọdo Oluwa yin ni o ti wa; nitorina eniti o ba fe ki o gbagbo, eniti o ba si fe ki o se aigbagbo, dajudaju Awa ti pese ina fun awon alabosi, ọgba re yoo rokirika won. Ti won ba wa atileyin, won yoo se atileyin fun won pelu omi kan ti o dabi idẹ ti won yọ, ti yoo se awon oju won, Mimu re buru, o si buru ni irogboku." Suratul Kahf:29.

7 . Deede ati tootọ (ododo):
Ninu awon ohun ti o se akunlowo titanka Isilaamu ni awon ohun ti o (Isilaamu) gba iroyin pelu won ninu deede ati rirorun agbọye re, ati ẹko re, ati nibi ibasepo re, eyi ti Ojise Ọlọhun -ki ike ai ola Ọlọhun maa ba á- salaye re pelu oro re pe:
“eyiti Olohun nife sijulọ ninu esin (iroyin esin) ni esin ti a se nitori Ọlọhun nikan soṣo ti o si je esin irorun." Al-Bukhari.
Nipaapa ilana Isilaamu ni imọmọ jẹ ẹmi omo-eniyan npa lori ohun ti ko ni agbara re yala ninu oro tabi ise. Bawoni ko se ni ribẹ nigbati o se pe o je esin adamọ ti kosi tako rara (ti kosi tako adamo) bi kii se pe o wa nibamusi pelu re, o si fun u ni anfani imaa se ijosin nibamusi agbara re, ati isesi re, eleyi l’ofa ti Ọlọhun fi wipe:
" وَمَا جَعَلَ عَلَيْكُمْ فِي الدِّينِ مِنْ حَرَجٍ "
".. Ko fi isoro kan si inu esin fun yin…" Surtul-Hajj:78.
Irorun Isilaamu yoo farahan nibi irorun idajo ati ijosin re, bakanna gbogbo irorun ati igbaye ti awon idajo ati ijosin ninu Isilaamu ko sinu lati lee ti ifunpinpin danu ati lati le kodi ilekoko ki gbogbo omo eniyan le ni ikapa lati se amuse won (awon idajo ati ijosin re). Gbogbo ase ati ijosin ninu Isilaamu wa nibamusi ikapa-ni omo eniyan ti kosi si ilabọ l’ọrun kọja ohun ti o nikapa re. Bakanna ki a lọ mọ pe awon aṣẹ ati ijosin wonyi yoo di ohun igbejusile ni awon asiko laluri ti idajo ọto si wa fun u. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
" فَمَنِ اضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ "
" …Sugbon eniti inira ba mu (je eran okun mbete, eje, ati elede) tiki i se niti ifẹ-inu re, ti ki i si se ikoja ẹnu ala, ko si ẹsẹ fun u…" Suratul Bakorah:173.
Eleyi ribe nitoripe o je ofin ti a fi ranse si omo eniyan ti won je eniti adinku ma mba won, ti won je eniti ikapa-ni won ni odiwọn, bayi lo fi jẹ’pe ofin shẹria Isilaamu ma nse akiyesi eleyi nitoripe o je ofin ti o wa ni ibamusi adamọ ọmo-eniyan ti Olohun da ni ọlẹ, gegebi Ọlọhun ti se alaye re pelu oro Re pe:
"يرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُخَفِّفَ عَنْكُمْ وَخُلِقَ الْإِنْسَانُ ضَعِيفاً "
" Ọlọhun fe lati se irorun fun yin, a si se eda eniyan ni ole." Suratu Nisai:28.
Awon ase ninu Isilaamu wa nibamu si ilana Oluwa yi, eleyi ti Ọlọhun se alaye re pelu oro Re pe:
" لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا لَهَا مَا كَسَبَتْ وَعَلَيْهَا مَا اكْتَسَبَتْ "
" Olohun ko gbe eru ti o ju enikan lọ le l’ori bi ko se bi agbara re ti mo, ti ẹ ni anfani isẹ ti ó ba se, ti ẹ na si ni ìyà ohun ti o ba se (laida)…" Suratu Bakorah:286.
Bakanna ni ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- na kanpa mọ pelu oro re pe:
" Ohun ti mo ba kọ fun nyin ẹ jina si (patapata) ohun ti mo ba si pa yin ni ase rẹ, ẹ se é bi ẹ ba ti ni agbara mo, dajudaju ohun ti o ko iparun ba awon ti o siwaju ni opọlopo ibere won ati iyapa won si awon Annabi won." Muslim.
Sugbon ki a lọ mọ pe dajudaju pe a ko l’ero pelu irọrun yin ìkó aayẹ ba erongba ofin shẹriah ati ẹsin. Kosi idiwọ ti yoo wa so eewọ di ẹto, ko si ilekoko ti yoo wa sọ ẹto di eewo, abi sisọwọ dẹngbẹre nibi lilo awon idajo re (esin islam) ati nibi sise amuse awon aṣe rẹ, tabi aayẹ nibi awon agboye Isilaamu ati awon ẹkọ (Aadab) apapọ, sugbon o je irorun ti o jina si ifunpinpin ati ilekoko ati ẹse ati iyapa (aṣe Ọlọhun). "Aaisha, iyawo Ojise Ọlọhun -ki Ọlọhun yonu si í- so pe: won ko ni so pe ki Ojise Ọlọhun o se asanya larin nkan meji (ninu awon alamori aye, abi alamori aye ati esin) ayafi ki o mu eyiti o rorun julo nigbati koba ti jẹ ẹsẹ, ti o ba je ẹse oun ni ẹniti yoo jina si julọ ninu ọmo eniyan." Al bukori ati muslim logba wa

8 . Pipe ati asepe:
Isilaamu ni esin ti o pe ti Ọlọhun si fi pe esin (re) ti O si fi se opin awon ofin ti o ti siwaju, ti o si je eyiti a fi pe idera, ti Ọlọhun si yonu si i (ni esin) fun awon eru Re. Ọlọhun ti ola Re ga julo sope:
" الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا "
"… Loni yi Mo se esin yin ni pipe fun yin atipe Mo se asepe idera Mi le yin lori, atipe Mo yonu si Islam ni esin fun yin…" Suratul Maida:3.
Pelu pipe yi, o je ohun ti a fi se iparẹ fun awon esin ti o siwaju re, Ọlọhun ko ni gba l’ọwo enikeni ninu awon eru re ki won sin í pẹlu esin ti o yato si i (Isilaamu). Awon ofin ti o siwaju je ofin ti o ni ipilẹ pipe ẹmi, ti o si ndoju oro ko ẹmi, ti o si npe é si fifo (kuro nibi aburu), sugbon koda si gbogbo ohun ti yoo tun gbogbo alamori isemi aye se ni ojuponna ti o pe pelu eto ati itosona ni ntoyatọ gedegede si Isilaamu ti o wa ni pipe, pelu fifi eto si gbogbo abala, aaye, ti o wa ko sinu alamori aiye ati esin. Nipaapa ojise ti Isilaamu, Annabi Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ti se alaye eleyi, atipe dajudaju esin l’ọdo Ọlọhun eyọkansoso ni, Ọlọhun gbe awon Annabi -ki alafia Ọlọhun maa ba won- dide nitori ki apakan won o le mo pe apa miran l’atori Annabi Nuhu -ki alafia maa ba á- titi de ori Annabi Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ti Ọlọhun fi se opin esin ti o si fi pe ofin shẹriah nibamusi oro re (ojisẹ Muhammad -ki ike Ọlọhun maa ba á) to lo bayi pe:
" dajudaju apejuwe èmi ati awon annabi ti o siwaju mi da gẹgebi arakunrin kan ti o kọ ile kan ti o si kọ daada ti o si se é l’ọso ayafi aye biriki kan ni ẹgbẹ kan (ti o fi silẹ lai se é daada) ni awon eniyan ba nrokirika ile na ti won si nse emo pelu’ẹ, won wa nsọpe bawo ni koba se dara to ti o ba lo gbe biriki si aye yi (aye to fi sile), o sọ pe (ojise Ọlọhun): èmi ni biriki yi, èmi ni opin awon Annabi." Al-Bukhari ati Muslim.
Lori eleyi (pipe ati asepe yi) Ọlọhun ti se adehun sisọ Isilaamu titi di asiko ti Ọlọhun yoo jogun ile ati ohun ti mbẹ lori re laise eleyi fun awon esin to siwaju rẹ, ti Ọlọhun kosi se adehun sisọ ọ fun won, nitoripe won jẹ esin ti a sọkale fun asiko kan gbogi, ti kosi si fun asiko miran, ati si awon ijọkan gbogi ti kosi si fun awon ijo miran ti o yato si won. Ọlọhun so bayi pe:
" إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ"
" Dajudaju Awa ni A sọ iranti na kalẹ atipe dajudaju Awa ni Olusọ fun u." Suratu Hijr:9.

9 . Hihan-de ati Yiye:
Dajudaju Isilaamu je esin ti o ye ti kosi darudapọ ati iruju ninu re. Eleyi je paapa ohun ti al-qur'ani ti o je ipile akoko fun ofin Isilaamu se alaye rẹ pe o jé tira ti o yanju ati imona fun omo eniyan, ati eri ti o ye, ti awon eleyi si je alaye fun hihan re. Ọlọhun so pe:
"قَدْ جَاءكُم مِّنَ اللّهِ نُورٌ وَكِتَابٌ مُّبِينٌ
"..dajudaju imọle lati ọdọ Ọlọhun ti wa ba yin ati Tira ti o yanju." Suratul-Maida:15.
Gbogbo eniyan ni o l’ẹto lati bere nipa ohun ti o ba ru l’oju tabi ti o nda lakai re laamu, kosi nkankan to kodi enikeni lati bere ohun ti ko baye é ninu Isilaamu, sugbon kofi aye eto idahun si awon ibere ti oniise pelu esin sile fun enikeni, bi kii se’pe o gbe eto idahun si awon alamori esin ati awon ti o sopọ mọ le awon onimimo ati awon eleko ofin shẹria lọwo, awon eniti o sepe won fi ẹmi sile lati wa imọ ati eko nipa awon nkan wonyi, a o gba ekọ imọ ilera lowo awon dokita, eko imọ ẹro lowo awon eleko re, a o si gba eko imo ofin shẹriah lowo awon to fi ara won le fun kiko re. Ọlọhun ti ola Re ga julo so bayi pe:
"وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ إِلاَّ رِجَالاً نُّوحِي إِلَيْهِمْ فَاسْأَلُواْ أَهْلَ الذِّكْرِ إِن كُنتُمْ لاَ تَعْلَمُونَ "
" Awa ko ran (enikeni) nisẹ siwaju re bikose awon okunrin ti A ranse si, nitorina ki e bi awon oni-iranti(oni-mimo) lere bi eyin ko ba mo." Suratu Nahl:43.
Kosi ninu Islam awon alamori ti oruju ti a si ni igbagbo si ti a ko si ni bere ohun to ruju lori re ayafi ohun ti lakai omo eniyan ko ba le gbe ninu awon alamori koko eleyi ti Oluwa wa ko se alaye re. Latara eleyi ni a o fi ri anfani igbagbo si ikoko eleyi ti Ọlọhun se eyin fun awon ti won ba ni igbagbo si í, ohun si ni aye igbedanwo ati imo iyato larin olugbagbo ododo si eniti ki i se olugbagbọ lododo. Olohun so bayi pe:
" الم ذَلِكَ الْكِتَابُ لاَ رَيْبَ فِيهِ هُدًى لِّلْمُتَّقِينَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِالْغَيْبِ وَيُقِيمُونَ الصَّلاةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنفِقُونَ والَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِمَا أُنزِلَ إِلَيْكَ وَمَا أُنزِلَ مِن قَبْلِكَ وَبِالآخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ أُوْلَـئِكَ عَلَى هُدًى مِّن رَّبِّهِمْ وَأُوْلَـئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ"
" Alif, Lam, Mim * Eleyi ni tira ti ko si iyemeji ninu re, o je itosona fun awon ti won nberu (Olohun). * Awon ti won ni igbagbo ninu ohun ti o pamo, ti won si ngberun duro, won si nna ninu ohun ti a pese fun won. * Awon ti won gba ohun ti a sokale fun o gbo, ati ohun ti a ti sokale siwaju re, won si ni amodaju nipa ojo ikeyin.* Awon wonyi ni eni itosona lati odo Oluwa won, awon wonyi si ni won o jere." Suratul Bakora:1-5.

10 . Irokan rere:
Ofin shẹriah ti Isilaamu je ofin to nfe rere niti adamo re, ki i se ofin ti a de pa ti o si ni ajosepo pelu awon ohun ti mbe ni ayika re ninu awujọ, tabi o je aburu si awon ohun ti oyika, bikosepe o jẹ ofin ti o gbaye ti si npasẹ imatan rere ka, ati ima nifẹ daada fun elomiran, ko to ki musulumi je eniyan rere fun ara re, bikosepe o se dandan ki o jẹ alatunse fun elomiran olùwà pelu awujo re, olutan rere ka ninu awujọ re, yoo ma kọ alaimokan ni ẹko, yoo mo to olusina si ona yoo ma pa ase daada yoo ma ko aburu yoo ma pepe si ibi ijosin fun Ọlọhun ati sise É ni Ọba-aso. Ọlọhun so pe:
"وَلْتَكُن مِّنكُمْ أُمَّةٌ يَدْعُونَ إِلَى الْخَيْرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَأُوْلَـئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ"
" E je ki ijo kan ma be ninu yin ti yoo ma pe (awon eniyan) sibi ise-rere ti won yoo si ma foro won sibi iwa eto ti won yoo si ma ko iwa ibaje, awon wonyi ni won o se orire." Suratu Aal-Imran:104.
Koda ofin shẹriah ninu Isilaamu se imaase rere si awon eniyan ati inife daada fun won ni okan ninu awon ohun ti won yoo pe ni ijosin (omo eniyan) nitori oro ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- to so pe:
" Maa fẹ fun awon eniyan ohun ti o fe fun ara re ki o le ba je musulumi." At tirmidhiy ati Ibn Majah.
Lati le se amuse irankan rere yi ati ise awon eniyan loju ọyin si í ni shẹriah ti Isilaamu fi se agbekale ola nla fun eniti ba ntan rere ka. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: Enikeni ti o ba pepe lo si ibi imona kan yoo gba esan (rere) ti o da gegebi esan awon eniti o te le (lori rere ti o pepe si) ti eleyi o si ni din esan won ku rara, atipe enikeni ti o ba pepe losi ibi isina kan yoo ni ese ti o da gegebi ese awon eniti won te le (nibi isina na) ti eleyi kosi ni din ese won ku rara." Muslim.

11 . Iduro sinsin ati ilosiwaju:
Dajudaju Isilaamu je esin to ba gbogbo asiko ati aye mu. Esin Isilaamu wa awon ipilẹ apapo ati awon opo alakotan ti won rinle ti won kosi gba yiyi ati idapo (pelu nkan miran) pelu yiyi asiko tabi aaye ninu adiokan ati ijosin gegebi irun ati onka awon raka re, ati awon asiko re ati zakah ati odinwon re, ati ohun ti o(zakah) je dandan ninu re, ati awe ati asiko re ati hajj ati bi a ti ń se é, ati asiko re ati ijiya toni aala, ati bẹẹbẹlọ. Awon ohun ti won ba je isele titun ninu awon nkan ti a ni bukata si, a o wo idajo won ninu Alukurani alaponle ati ninu awon Hadisi ti o f’ese rinle lati odo ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ti a ba ri idajo na ninu awon mejeji a o gba mu, a o si ni gbojuwo nkan miran mo, ti a ko ba ri idajo na nibe a o wa si inu awon igbiyanju awon Alufa ti won je eni- Ọlọhun ni gbogbo asiko ati aaye nibamu si ohun ti yoo mu anfani apapo wa ti yoo si ba igba won mu ati ipo awujo won latara sise agbeyẹwo si ohun ti oseese ki Al-kur'ani ati sunnah o ko sinu, ati sise agbeyewo awon ohun isele titun lori awon opo, ilana, ati ofin shariah alapaapo eyiti a yo lati inu Al-kur'ani ati sunnah ni aniyan a ti ri ohun ti yoo se omo eniyan ni anfani laini tako ẹri shẹriah kankan, ki Isilaamu le ba gbogbo asiko mu, ki o si le ba maa yi pelu ohun ti eyikeyi awujo ni bukata si.

12 . Pipe ni gbogbo abala:
Dajudaju Isilaamu ma njẹpe si gbogbo ohun ti omo eniyan ba ni bukata si ni ti ẹmi ni tabi ti ara, pelu iwontunwonsi ti ó si ti irekoja-ala danu ni gbogbo ona. Ọlọhun ti ola ga julo so pe:
"وَابْتَغِ فِيمَا آتَاكَ اللَّهُ الدَّارَ الْآخِرَةَ وَلَا تَنسَ نَصِيبَكَ مِنَ الدُّنْيَا وَأَحْسِن كَمَا أَحْسَنَ اللَّهُ إِلَيْكَ وَلَا تَبْغِ الْفَسَادَ فِي الْأَرْضِ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ"
" Wa ile ti orun ohun ti Ọlọhun fun ọ, ki o ma si se gbagbe ipin re ni aye ki o si ma se daradara gegebi Ọlọhun se se daradara fun iwo na, ma se wa lati se ibaje lori ile dajudaju Ọlọhun ko feran awon onibaje." Suratul Qasas:77.
Ẹmi omo eniyan ni iwoye si Isilaamu je ohun ti Ọlọhun da ti o si fi se arole lori ile lati le ma se ijosin fun U, ati lati lo ofin re. O si da ara fun ẹmi yi ni pipe ti o sopọ mo ara won nitori ki emi le pe ohun ti Ọlọhun pa á lase ki o se ninu awon ijosin ati awon eto ati lilo ilẹ eyiti Ọlọhun se é ni arole le lori. Ọlọhun ti ola re ga julo so pe:
" وَهُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلاَئِفَ الأَرْضِ وَرَفَعَ بَعْضَكُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ لِّيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ إِنَّ رَبَّكَ سَرِيعُ الْعِقَابِ وَإِنَّهُ لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ "
" On na ni eniti O se yin ni arole lori ile, O si gbe apakan yin ga niyi ju apakan lo, nitori ki O le dan yin wo nipa ohun t O fun yin, dajudaju Oluwa re yara lati san esan iya, On na si ni Alaforijin, Alanu." Suratu-l- An'am:165.
Ko si aṣa aimani iyawo ati asa imo se ijosin nikan, ati gige ara eni kuro nibi ohun igbadun aye, eleyi ti Ọlọhun da fun awon eru Re ti O si se é ni eto fun won. Ọlọhun so bayi pe:
"قُلْ مَنْ حَرَّمَ زِينَةَ اللّهِ الَّتِيَ أَخْرَجَ لِعِبَادِهِ وَالْطَّيِّبَاتِ مِنَ الرِّزْقِ قُلْ هِي لِلَّذِينَ آمَنُواْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا خَالِصَةً يَوْمَ الْقِيَامَةِ كَذَلِكَ نُفَصِّلُ الآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ "
" Wipe: Tani eniti o se lewo oso ti Ọlọhun, eyiti O mu jade fun awon erusin Re ati awon ohun ti o dara ni ipese? Wipe: awon nkan wonyi wa fun awon eniti o gbagbo ni ododo ni ile aiye yi, sugbon ti won nikan soso ni ojo ajinde, bayi ni Awa nse alaye awon ami na fun awon eniyan ti o ni mimo." Suratul Aaraf:32.
Ni idakeji kii se esin wiwa-aiye ati jijindo si inu yodoyindin ati igbadun re laisi onde kankan, sugbon Isilaamu je esin deede (ti ko yeba si otun tabi si osi) ti o si se akojo larin esin ati aiye ti kosi gbe ola fun ọkan lori ekeji. Nipaapa Ọlọhun ti pase sise deede larin emi ati ara, O si pe musulumi lasiko ti o ba jindo si inu aye pe ki o ma se ayewo bukata emi re pelu ki o ma se ohun ti Ọlọhun se ni oranyan le lori ninu awon ijosin. Ọlọhun so bayi pe:
"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نُودِيَ لِلصَّلَاةِ مِنْ يَوْمِ الْجُمُعَةِ فَاسْعَوْا إِلَى ذِكْرِ اللَّهِ وَذَرُوا الْبَيْعَ ذَلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ"
" Eyin onigbagbo ododo! Nigbati won ba pepe si irun ni ojo jimah ki e sare tete losi ibi iranti Ọlọhun ki e si fi tita-rira sile, eleyi ni ore fun yin ti eyin ba je eniti o mo." Suratul Jum'ah:9.
A si fe lowo ni asiko ti o ba ti jindo si inu ijosin pe ki o ranti bukata re si ohun igbadun aye ninu sise ise ati wiwa arisiki. Ọlọhun so pe:
" فَإِذَا قُضِيَتِ الصَّلَاةُ فَانْتَشِرُوا فِي الْأَرْضِ وَابْتَغُوا مِنْ فَضْلِ اللَّهِ وَاذْكُرُوا اللَّهَ كَثِيرًا لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ "
" Nitorina nigbati e ba pari irun na tan, e tuka si ori-ile ki e si ma wa kiri ore-ajulo Ọlọhun, ki e si ma ranti Ọlọhun pupo, ki e le jere." Suratul Jum'ah:10.
Isilaamu se eyin lori eniti o ba se adapo larin awon iroyin mejeji yi. Ọlọhun ti ola Re ga julo sope:
"رِجَالٌ لَا تُلْهِيهِمْ تِجَارَةٌ وَلَا بَيْعٌ عَنْ ذِكْرِ اللَّهِ وَإِقَامِ الصَّلَاةِ وَإِيتَاءِ الزَّكَاةِ يَخَافُونَ يَوْمًا تَتَقَلَّبُ فِيهِ الْقُلُوبُ وَالْأَبْصَارُ "
" Awon eniyan ti won ko je ki tita-rira di awon lowo iranti Olohun, ati lati kirun ati lati yo zaka, won nberu ojo kan ti awon okan yoo ma yi sotun-sosi ninu re ati awon oju." Suratu Nur:37.
Isilaamu sọ awon eto emi ati ara nibamusi ofin shẹriah Ọlọhun ti kosi si ikoja-ala ati aseeto ninu re. Musulumi gegebi a se fe ki o ma so emi re ki o si ma se isiro re lori awon isesi re ati lori gbogbo ohun ti o ba n se nise;
" فَمَنْ يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًا يَرَهُ (7) وَمَنْ يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُ (8) "
" Enikeni ti o ba se ise rere ti o kere bi omọna-gun yoo ri (esan) re* “Atipe enikeni ti o ba se ise buburu kan bi omo na gun yoo ri (esan) re." Suratu Zilzaal: 7-8.
Gegebẹ na ni a se fe ki ó se amojuto ara re nibi gbigbadun pelu ohun ti Ọlọhun se ni ẹto fun u ninu awon ohun ti o dara ni jije ati mimu ati ni wiwo ati ni fife (obirin), a si se ohun deede si awon ohun daradara yi pelu ima maa se ikoja-ala nibẹ, eleyi ti aburu re lori ara ko pamọ. Ọlọhun ti ola Re ga julo sope:
" وَكُلُوا وَاشْرَبُوا وَلَا تُسْرِفُوا إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ"
"…E maa jẹ, ẹ maa mu, ki e si mase koja ala (nibe) dajudaju Ọlọhun ko feran awon olukoja-ala." Suratul A'raf:31.
Isilaamu ka sise awon nkan wonyi leewo si ọkan ninu awon ohun ti o je eewo ninu ofin shẹriah. Anas omo Maalik -ki Ọlọhun yonu si- so pe:
" awon eniyan meta kan wa si awon ile awon iya ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ni eniti won nbere nipa ijosin Annabi -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- nigbati won fun won niro nipa re (ijosin re) ni won ba kare re, won ba sope: tani awa ni egbe ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- eniti won ti fi ori ẹse re to kọja ati eyi ti mbọ jin. Okan ninu won ba sope: emi o ma fi gbogbo oru kirun lailai, omiran tun sope: emi o ma fi gbogbo odun gba awe mi o ni sinu, iketa na ba sope: emi koni sunmo obirin, un ko si ni fe iyawo lailai, ni Ojisẹ Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ba jade si won, ni o ba so wipe: eyin ni eniti o so bai bai, amo mo fi Ọlọhun bura emi ni mo paya Ọlọhun ju yin lo, emi si ni mo beru Re ju yin lo sugbon emi ma ngba awe mo si ma sinu, mo ma nkirun mo si ma nsun, mo si nfe obirin, enikeni ti o ba gunri kuri nibi Sunnah mi kii se ara mi. Al-Bukhari.

13 . Itesiwaju ati Imo seku:
Pelu pe dajudaju ofin shẹriah ti Isilaamu je opin awon ofin sanma ati ipari won nitori pe o ko gbogbo ilana eko Ọlọhun patapata ti o ba gbogbo asiko ati aye mu sinu. Ọlọhun ti se é ni esin ti yoo ma lọ gbere ti yoo si ma tesiwaju titi Ọlọhun yoo fi jogun ile ati ohun to mbe lori re, O si se adehun siso re ti ayipada tabi yiyi kankan kosi nii kan, ti eleyi kosi si fun awon ofin ti o siwaju re. Al-Qur'anu ni ipile akoko fun ofin shẹriah, Ọlọhun si se adehun iso fun u kuro ni bi ki won se alekun ohun ti ko si ninu re si, abi ki won se adinku ohun ti mbe ninu re, o je nkan iyanu ti yoo ma seku gbere ti ojise Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ni iyato si awon nkan iyanu awon ojise to siwaju re eleyi ti ko ni si mo ti asiko awon Annabi na ba ti tan, ti yoo si je eri lori ije ododo ohun ti a fi ranse si won ni asiko re, ti eniti o ba mbe ni asiko re si gbodo gbaagbo, amo Alukurani je iyanu ti a o ma ka titi di asiko ti aye ko ni je aye mo, o si je eri lori ododo ti a fi ran Ojise nla Muhammad -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-, Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
"إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ"
" Dajudaju Awa ni A so iranti kale, dajudaju Awa si A je Oluso fun u." Suratul Hijr:9.
Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: " ijo kan ninu awọn olutẹle mi koni ye koni gbo ti yoo ma wa lori ododo ti a o si ma ranlowo, ti awon ti won ba yepere won ati awon ti won yapa si won koni ko ipalara ba won titi di ojo igbehinde." Muslim
Eleyi ni ohun ti a nri nibi yiyipada opolopo awon elesin miran si inu Islam ati kikere awon ti njade kuro ninu re leyin ti won ti wo inu re, pelu pe ina owo lori titanka re le pupo, be si ni inawo nanra po lori ati gbe ogun ti i, ati lati di ona mo ati lati so lorukọ buruku lodo awon ota re.

14. Akotan:
Esin Isilaamu se akotan gbogbo abala isemi aye, o si wa pelu awon eto ati ofin eyiti yoo mu awujo rere wa, kosi abala kankan sile ninu awon abala isemi aye omo eniyan pelu gbogbo ipin re yala ẹmi ni tabi ara, ẹsin ni tabi isemi aye, eyo eniyan kọọkan ni tabi apapọ eniyan ayafi ki o gbe ilana rere lele fun u. Olohun so pe:
" وَنَزَّلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ تِبْيَانًا لِكُلِّ شَيْءٍ وَهُدًى وَرَحْمَةً وَبُشْرَى لِلْمُسْلِمِينَ"
" …Awa si so Tira na kale fun o ti o je alaye fun gbogbo nkan ati ona mimo ati anu ati iro idunnu fun awon ti o ju ara won sile fun Ọlọhun (Musulumi). Suratu An nahal: 89.
Isilaamu se amojuto ajosepo musulumi pelu Oluwa re, ati pelu awujo re ati agbegbe to rokirika re. Ninu ohun ti ntoka si akotan yi ni akolekan Isilaamu pelu eyiti okere ju ninu iwa ti o nii se pelu isemi aye omo eniyan. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-so pe: “Ipin igbagbo je metaleladorin tabi metalelogota, eyiti o lore julo (ninu egbawa miran: eyiti o ga julo) ni gbolohun (La ilaha illa Lahu), eyiti o si kere julo ni imu suta (ohun ti o le fa suta) kuro ni ona, atipe itiju je ipin kan ninu igbagbo. Bukhari ati Muslim.
Pelu akotan yi, Isilaamu je esin to gba iroyin pelu awon ohun to mboyi;
    Sise aponle fun omo eniyan pelu pe Ọlọhun gbe ola fun u lori gbogbo eda ninu ile aye yi, O si ro won fun u. Olohun so pe:
"ولَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِّمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلاً"
" Atipe dajudaju Awa se aponle fun awon omo annabi Adamo, Awa gbe won rin lori ile ati odò, Awa si fun won ni ije-imu ninu awon ohun ti o dara, Awa si da won lola ju opolopo ninu awon eda ti A da niti ola" Suratu Israi:70.
    Imo ara eni: Isilaamu se wa ni oju ọyin si imaase ajosepo rere pelu awujo musulumi ati awon awujo to rokirika wa nibi ajogbe pelu rere, ati sise daada, ati inife dada (fun alajogbe), ati imaase pasiparo anfani (pelu alajogbe). Ọlọhun ti ola re ga julo so bayi pe:
" يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوباً وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ"
" Eyin eniyan, dajudaju A da yin lati ara okunrin ati obirin, A si se yin ni orile ede ati iran-iran ki e le ba ma mo ara yin. Dajudaju eniti o ni ola ju lodo Ọlọhun ninu yin ni eniti o paiya (Re) ju, dajudaju Ọlọhun ni Oni-mimo Alamotan." Suratu Hujuraat:13.
    Sise amojuto awujo nigbati o se pe a se é ni oranyan lori musulumi pe ki o ni akolekan pelu alamori awon omo iya re lori gbogbo ilekoko. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: a o ri awon olugbagbo lododo nibi ike larin ara won, ati nibi ife larin ara won, ati nibi ajosepo larin ara won ti won yoo da gegebi ara kan to se pe nigbati orike kan (ninu re) ba nke eta-ero gbogbo ara re to ku na yoo keta-ero pelu airorunsun ati ara gbigbona. Al bukhori ati mulim logba wa.
    Ominira ti a de pelu onde esin, eleyi ti yoo yọ ọ jade kuro nibi ominira eranko ti ko ni onde. Latara ominira yi, o wa fun gbogbo (eniyan) awon ohun ti mbo yi:
a. Ominira ironu ati ise afihan irori pelu awon onde re. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَقُولُوا قَوْلًا سَدِيدًا "
" Eyin olugbagbo lododo, e beru Ọlọhun, ki e si ma so oro to dogba (oro rere)." Suratul Ahzaab:70.
b. Ominira ini nkan ati wiwa owo ni ona ti o tọ (Halal). Olohun so pe:
" لِلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِمَّا اكْتَسَبُوا وَلِلنِّسَاءِ نَصِيبٌ مِمَّا اكْتَسَبْنَ "
"… Ipin mbe fun awon okunrin ninu ohun ti won nse, ipin sin be fun awon obirin ninu ohun ti won nse.." Suratu Nisai:32.
c. Ominira imọ ati wiwa imọ, Ojisẹ Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: " wiwa mimọ oranyan l’oje lori gbogbo musulumi." Ibn Majah.
d. Ominira sise anfaani ninu ohun ti Ọlọhun se eda si inu aye yi ninu daada, Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
"هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ ذَلُولًا فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِنْ رِزْقِهِ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ
" Oun ni Eniti O se ilẹ fun nyin ni rirọ, nitori ki e le maa rin ni awon agbegbe re, ki e si ma je ninu ipese Re, ọdo Re si ni igbedide gbogbo eda." Suratul Mulk:15.
    Pipese ifokanbale alakotan, eleyi ti o ko awon ohun ti mbo yi sinu:
a. Ifokanbale lori esin, pelu pe ki a ma mu orogun pelu’ẹ, ati pipepe si ibi ijosin re sinu,Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
"وَقَاتِلُواْ فِي سَبِيلِ اللّهِ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَكُمْ وَلاَ تَعْتَدُواْ إِنَّ اللّهَ لاَ يُحِبِّ الْمُعْتَدِينَ "
" Ki e si maa ba won ja loju ona Ọlọhun awon eniti o mba yin ja, sugbon ki e mase rekoja ala, dajudaju Ọlọhun ko feran awon ti o nrekoja ala." Suratul Bakorah:190.
b. Ifokanbale lori emi, Ọlọhun t’ola Re ga julo so pe:
"وَمَن يَقْتُلْ مُؤْمِناً مُّتَعَمِّداً فَجَزَآؤُهُ جَهَنَّمُ خَالِداً فِيهَا وَغَضِبَ اللّهُ عَلَيْهِ وَلَعَنَهُ وَأَعَدَّ لَهُ عَذَاباً عَظِيماً "
" Eniti o ba mọọmọ pa onigbagbo ododo kan, esan re ni ina, yoo se gbere ninu re, Ọlọhun yoo si binu si i, O si sẹ ibi le e, o si pese iya ti o tobi fun u." Suratu Nisai:93.
c. Ifokanbale lori owo, Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
" وَلاَ تَأْكُلُواْ أَمْوَالَكُم بَيْنَكُم بِالْبَاطِلِ وَتُدْلُواْ بِهَا إِلَى الْحُكَّامِ لِتَأْكُلُواْ فَرِيقاً مِّنْ أَمْوَالِ النَّاسِ بِالإِثْمِ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ"
" E ko gbodo je ohun-ini yin larin ara yin pelu eeru ati lati mu ninu re fi wa ona are lodo awon oludajo ki e ba le je apakan ninu ohun-ini awon eniyan pelu iwa ese, beni eyin mo." Suratul Bakorah: 188.
d. Ifokanbale lori omoluabi, Ọlọhun ti ola Re ga julo so bayi pe:
" وَلاَ تَقْرَبُواْ الزِّنَى إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَسَاء سَبِيلاً "
" E ma se sunmo sina (agbere), dajudaju o je iwa aimo, o si buru ni oju ona." Suratu Israi:32.
e. Ifokanbale lori lakai kuro nibi awon ohun ti o le se ni suta ninu oti ati nkan oloro, Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالأَنصَابُ وَالأَزْلاَمُ رِجْسٌ مِّنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ "
" Eyin onigbagbo ododo, dajudaju oti ati tete-tita ati orisa-bibo ati fifi ofa pin nkan je egbin ninu ise esu, nitorina e jinna si í, ki e le se orire." Suratul Maida:90.
    Ise afirinle awon ẹto nigbati o se pe Isilaamu se awon eto ni oranyan larin awon eniyan nibamusi yiyato ipo won nitori ki won le ma gbe pelu irepo ati ife, bayi ni awon anfani esin yoo ma sele larin won ti alamori isemi aye won yoo si ma lo leto-leto. Awon eto yi pin si meji;
a. Awon ẹto adani, Ọlọhun so pe:
" وَاعْبُدُواْ اللّهَ وَلاَ تُشْرِكُواْ بِهِ شَيْئاً وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً وَبِذِي الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينِ وَالْجَارِ ذِي الْقُرْبَى وَالْجَارِ الْجُنُبِ وَالصَّاحِبِ بِالجَنبِ وَابْنِ السَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ إِنَّ اللّهَ لاَ يُحِبُّ مَن كَانَ مُخْتَالاً فَخُوراً "
" E maa sin Ọlọhun, ki e si ma da nkankan po mọ Ọ, ki e si maa se rere si awon obi yin mejeji, ati awon ibatan ti o sunmo yin, ati awon omo-orukan, ati awon alaini, ati awon aladugbo ti o sunmo yin, ati awon aladugboti o jinna ati awon ore alabarin, ati omo oju ona ati awon ti owo otun yin ni ikapa le won lori, dajudaju Ọlọhun ko feran awon onigberaga onifaari." Suratu Nisai:36.
b. Awon ẹto alajoni, Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe:
" e ma se ma se keta ara yin, e ma se ma se alekun owo oja ( ti e ko gbero lati ra bikosepe nitori ati se l’ọso loju eniti o fe ra) larin ara yin, e ma se ma binu ara yin, e ma se ma kọyin si ara yin ( e ma maa mu ara yin ni ota), ki apakan ninu yin ma se ra oja apakan (oja ti apakan yin ti gbero lati ra), e je erusin Ọlọhun ni omo-iya, Musulumi omo-iya musulumi ni, ko gbodo se abosi re, ko gbodo yepere re, ko gbodo f’oju kere re, ipaya (Ọlọhun) wa ni ibi yi, o si na owo si igbaaya re ni ẹẹmeta, o to fun omo eniyan ni aburu ki o fi oju kere omo-iya re musulumi, o je eewo fun musulumi si musulumi ẹje re, dukia re, ati omoluabi re." Muslim.
    Ikẹ eleyi ti o ko gbogbo eda sinu. Ninu ike yi;
a. Imo lo pelu ike pelu gbogbo omo eniyan, ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe:
" Ọlọhun yoo ke awon oluke-eda, e ma ke awon ohun ti nbe lori ile eniti nbe ni sanmo yoo ke yin, okun-ebi je eka kan ti o sopọ mọ Al-arasi Oba- Onike, eniti o ba so ó pọ, Ọlọhun yoo so ó po, eniti o ba ge é, Ọlọhun yoo ge oun na.' Ahmad, Abu Dawood, ati Al-Hakim.
b. Imo lo pelu ike pelu awon eranko nitoripe lilo pelu ike pelu won je okunfa aforijin ese ati wiwo ogba-idera. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-so pe:
" Larin igbati arakunrin kan fi wa lori irin ni ogbe ba mu ni o ba ri kanga kan ni o ba wo inu re ti o si mu omi leyinna o jade, ni aja kan ban la enu ti o si npan ilẹ la latara ebi, ni arakunrin yi ba so pe: ogbẹ ti ngbe aja yi ni iru ogbe ti o gbe emi na ni o ba ko si inu kanga na ti o si kun bata re pelu omi, ni o ba fun aja yi ni omi mu, ni Ọlọhun ba dupe fun, o si fi ori ese re jin. Won sope: Ire ojise Ọlọhun! unje esan (rere) nbe fun wa nibi awon eran osin ni? O sope: beni, lori gbogbo eran abaye ni esan wa." Bukhari ati Muslim.
    Igbimoran nitoripe Islam pa awon olutele ni ase pe ki won mu (igbimoran) ni ilana ti won o ma tele nibi gbogbo alamori esin ati isemi aye larin ara won ati pelu awon ara ita. Ọlọhun ti ola Re ga julo sope:
"فَبِمَا رَحْمَةٍ مِّنَ اللّهِ لِنتَ لَهُمْ وَلَوْ كُنتَ فَظّاً غَلِيظَ الْقَلْبِ لاَنفَضُّواْ مِنْ حَوْلِكَ فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاسْتَغْفِرْ لَهُمْ وَشَاوِرْهُمْ فِي الأَمْرِ فَإِذَا عَزَمْتَ فَتَوَكَّلْ عَلَى اللّهِ إِنَّ اللّهَ يُحِبُّ الْمُتَوَكِّلِينَ
" Nitori anu a ti odo Ọlọhun wa ni iwo fi ro funwon, ibasepe o je oniwa buburu ati olokan-lile ni won ka ti tuka kuro lodo re, nitorina mojukuro fun won ki o si toro aforijin fun won, ki o si ma ba won jiroro nipa alamori na, bi o ba si pinnu tan ki o gbekele Ọlọhun, dajudaju Ọlọhun feran awon olugbekele (Ọlọhun)." Suratu Aal-Imran:159.
    Dogbandogba larin awon eniyan lapaapo nibi siseda ati rire ako won ni, tabi abo, funfun won ni tabi dudu won, larubawa won ni abi eyiti ki i se larubawa, kosi iyato larin won ayafi pelu iberu Ọlọhun. Ọlọhun so pe:
" يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَاءً وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي تَسَاءَلُونَ بِهِ وَالْأَرْحَامَ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا "
" Eyin eniyan: e beru Oluwa yin, eniti O se eda nyin lati ara emi kansoso,O si se eda aya re lati ara re, O si tan opolopo okunrin ati obirin kale lati ara awon mejeji, ki e si beru Ọlọhun, eniti e fi mbe ara yin ati okun ibi, dajudaju Ọlọhun je Oluso lori yin." Suratu Nisai:1.
    Deede ti o kun, ni ibamusi agboye re alapapo pelu emi ati eniyan, Olohun ti ola Re ga julo so pe:
" إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغْيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُون"
" Dajudaju Ọlọhun pa lase sise deede, ati rere, ati ima fun awon alasunmo ni etọ won, O si nko fun ni iwa ibaje ati iwa buburu ati rukerudo, O n se ikilo fun nyin ki e le ba gba ikilo." Suratu Nahl:90.
    Alafia ti o kun lori ara inu-ile ati pelu ara-ita, Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun ma ba- so pe:" nje ki ń fun yin niro nipa olugbagbo lododo, oun ni eniti awon eniyan fokanbale si i lori dukia won ati ẹmi won, musulumi ni eniti awon eniyan la kuro nibi enu re ati owo re, olugbiyanju ni eniti o ja emi ara re logun si ibi itele ase Ọlọhun, oluyan-odi ni eniti o yan iyapa (ase Olohun) ati ese lodi." Ahmad ati Ibn Hibban.
    Iseni loju ọyin lori ise ati wiwa owo ni ona ti o to. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á – so pe:" Ki enikookan ninu nyin o mu okun ki o wa fi gbe igi-isepe si eyin re ki o wa lo ta á, ki Ọlọhun wa fi la á (kuro nibi iyepere ima tọro) ni oore fun u ju ki o ma toro lodo awon eniyan, won fun ni o, tabi won ko fun u. Al-Bukhari.
    Imora: Sise imototo je ohun ti a se loju ọyin (fun wa), ti a si pa ase re nibamusi awon ohun ti nbo yi;
a. Sise imora enu leyin jije, ati sise akolekan pelu imototo eyin ati enu pelu sise wa loju ọyin lilo pako, nitori oro ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- ti o so pe:" ti kii ba se pe ki ń ma ko inira ba yin, un ba pa yin lase lilo pako nibi gbogbo irun.' Muslim.
b. Sise imora gbogbo ohun ti o le je aaye fun kokoro aisan ati idoti. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: " nkan marun kan ninu ilana (awon Annabi) lowa, dida abe, gige irun abe, titu irun abiya, gige irun tubomu, ati gige ekanna. Bukhari ati muslim.
c. Sise imora oju ara mejeji. Salman -ki Ọlọhun yonu si –so pe: ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- kọ fun wa pe ki a ma dojuko gabasi fun yiyagbẹ, tabi itọ, tabi ki a ma se imora pelu ọwo ọtun, tabi ki a ma se imọtoto pelu ohun to kere si okuta meta, tabi ki a ma se imọtoto pelu igbẹ tabi egungun." Muslim.
d. Ima lo asọ to rẹwa to mọ, ati nkan oloorun didun. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
" يَا بَنِي آدَمَ خُذُوا زِينَتَكُمْ عِنْدَ كُلِّ مَسْجِدٍ "
" Eyin omo Adamo, e ma se ọṣo yin nigba yowu ti e ba nlọ si aaye ijosin…" Suratul A'raf:31.
    Imototo nitoripe opolopo ijosin ni o nii se pelu re, o si pin si imototo afoju ri ati imototo alaifoju ri.
a. Imototo afojuri ni imototo ara kuro nibi egbin, nitoripe o je majemu kan fun dida ati gbigba apakan awon ijosin, A se sise aluwala ni okan ninu awon majemu dida irun eleyi ti musulumi nki ni emarun lojumo. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe:" a ko ni gba irun kankan lai si imora, ati saara ti a ji (ohun ti a fi se sara na)." Muslim.
A se wiwẹ iwe janaba ni oranyan ni eyin egbin ara, nitori oro Ọlọhun to so bayi pe:
" وَإِنْ كُنْتُمْ جُنُبًا فَاطَّهَّرُوا "
"…ti eyin ba je elegbin ara ki e se imora.." Suratul Maida:6.
A si se ninu ilana ti a kan pa mo fun apakan awon ijosin gegebi irun jimo ati odun mejeji (odun awe ati ileya) ati hajj, ati umura, ati bebelo.
b. Imora ti a ko le foju ri nibi ki a se afomo emi kuro nibi ebo sise. Olohun ti ola Re ga julo so pe:
"E maa sin Ọlọhun, ki e si ma se orogun pelu Re…"
Abi sekarimi. Ọlọhun so pe:
" فَوَيْلٌ لِلْمُصَلِّينَ * الَّذِينَ هُمْ عَنْ صَلَاتِهِمْ سَاهُونَ* الَّذِينَ هُمْ يُرَاءُونَ* وَيَمْنَعُونَ الْمَاعُونَ "
" Egbe ki o ma ba awon olukirun* Awon ni awon oluso okan kuro nibi irun won * Awon na ni alasehan (onise-karimi)* Won si ma nko nkan ajọlo fun awon eniyan" Suratul Ma'uun:4-7.
Abi ijora-eni loju. Olohun so pe:
" وَلَا تُصَعِّرْ خَدَّكَ لِلنَّاسِ وَلَا تَمْشِ فِي الْأَرْضِ مَرَحًا إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ"
" Mase gbe parike re kuro lodo awon eniyan (ma se gunri kuro lodo awon eniyan niti ifojudi), ma si se ma rin ni ori-ile niti fari, dajudaju Ọlọhun ko feran gbogbo onigberaga onifaari." Suratu Luqman:18.
Abi igberaga ati fari. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-so pe:" Koni wo ọgba-idera eniti ohun to kere bi omo-inagun igberaga wa ninu okan re. Arakunrin kan ba so pe: ire ojise Ọlọhun! Dajudaju arakunrin kan ti o ni fe ki aso ati bata re ma rewa, O dahun wipe: dajudaju Ọlọhun, Oba to rewa Ni, O si feran ẹwa, igberaga ni kikọ ododo, ati kikere awon eniyan" Muslim.

15 . Iwa rere:
Isilaamu je esin iwa rere ati gbogbo dada iwa rere. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: " dajudaju won gbe mi dide lati pe iwa rere." Ahmad ati Bukhari.
Kosi iwa rere Kankan ayafi ki Isilaamu pa ase sise re, yoo si tun se wa ni oju-ọyin si í, kosi iwa buburu Kankan ayafi ki Isilaamu ko ọ fun wa, yoo si tun pewa lakiyesi pelu re, ni sise alaye ilana apapo eleyi ti musulumi yoo ma rin lori re nibi ajosepo re pelu awujo re ati awon eniyan miran. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-so pe: " jina si awon nkan ewo, ki o je oluberu Ọlọhun ju lo, yonu si ohun ti Ọlọhun pin fun o, ki o je alayo-okan julo, maa se rere si alabagbe re, ki o je olugbagbo ododo, maa fe fun awon eniyan ohun ti ohun fe fun ara re, ki o je musulumi, ma pọ ni erin keeke, dajudaju opolopo erin keeke ma npa okan." Tirmidhi ati Ahmad.
Nititori ki ilana yi le ba rinle ni okan ni o fi se alaye opin irin-ajo buburu fun eniti o seri kuro nibe (nibi ilana). Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: " nje e mọ eniti opofo? Won so pe: eniti opofo ninu wa ni eniti ko ni owo sile ati dukia, ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- so pe: eniti opofo ninu ijo mi ni eniti o wa ni ojo igbehinde pelu irun, ati saka, ati awe, o ba wa ni eniti o ti bu eleyi, o le eleyi ni oko aburu, o ta eje eleyi le, o na eleyi, a ba eleyi ninu ise rere re, ati eleyi ninu ise rere re, dajudaju ti ise rere re ba tan saju ki o pe ẹto awon eniti mbe lorun rẹ, a o mu ninu ẹse wọn, a o si gbele lori, leyinna a o fi si inu ina." Muslim.
Isilaamu npepe si igbedide awujo ti yoo fara ro ara won, ti yoo si je awujo onike larin ara won, ti yoo duro lori ife ati imaase anfani fun elomiran latara awon ilana yi. Isilaamu je esin iwa rere ati eko (ladabi) pelu Ọlọhun, ati awon ojise Re, ati awon eniyan lapaapo nibamusi agboye re alapaapo. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا يَسْخَرْ قَومٌ مِّن قَوْمٍ عَسَى أَن يَكُونُوا خَيْراً مِّنْهُمْ وَلَا نِسَاء مِّن نِّسَاء عَسَى أَن يَكُنَّ خَيْراً مِّنْهُنَّ وَلَا تَلْمِزُوا أَنفُسَكُمْ وَلَا تَنَابَزُوا بِالْأَلْقَابِ بِئْسَ الاِسْمُ الْفُسُوقُ بَعْدَ الْإِيمَانِ وَمَن لَّمْ يَتُبْ فَأُوْلَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيراً مِّنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ وَلَا تَجَسَّسُوا وَلَا يَغْتَب بَّعْضُكُم بَعْضاً أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَن يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتاً فَكَرِهْتُمُوهُ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَّحِيمٌ "
" Eyin olugbagbo ni ododo, ki awon eniyan mase ma fi awon eniyan kan se yeye, o le jepe won dara ju won lo (lodo Ọlọhun, ki obirin mase yeye obirin, o le je pe won dara ju won lọ, e ko gbodo bu ara yin, e ko si gbodo pe ara yin ni oriki buburu, aidara ni oruko buburu leyin igbagbo ododo, eniti ko ba ronupiwada awon eleyi ni alabosi.* Eyin ti e Gbagbo ni ododo e jinna si opolopo abadida, dajudaju apakan abadida je ese ni, e ma se ma topinpin ara yin, ki apakan yin mase pegan apakan leyin, nje okan ninu yin wa fe lati je eran omo iya re niti oku nbete? Eyin korira eyi, ki e paiya Ọlọhun, dajudaju Ọlọhun je Olugba-ironupiwada Onike" Suratul Hujuraat:11-12.
Esin Isilaamu je esin gbafi-pamo nibamusi agboye re alapaapo, igbafi-pamo larin musulumi ati Oluwa re, larin re ati awon eniyan. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
"إِنَّ اللّهَ يَأْمُرُكُمْ أَن تُؤدُّواْ الأَمَانَاتِ إِلَى أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُم بَيْنَ النَّاسِ أَن تَحْكُمُواْ بِالْعَدْلِ إِنَّ اللّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُم بِهِ إِنَّ اللّهَ كَانَ سَمِيعاً بَصِيراً"
" Dajudaju Ọlọhun npa lase fun yin pe ki e da ohun ti a fun yin toju pada fun awon ti o ni won, nigbati e ba ndajo larin awon eniyan e da a pelu deede, dajudaju Ọlọhun dara ni Oluse ikilo, dajudaju Ọlọhun je Olugboro Oluriran." Suratu Nisai:58.
Isilaamu je esin ododo, Ọlọhun so bayi pe:
"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ اتَّقُواْ اللّهَ وَكُونُواْ مَعَ الصَّادِقِينَ "
" Eyin onigbagbo ni ododo e paiya Ọlọhun, ki e si ma wa pelu awon olododo." Suratu Taobah:119.
Isilaamu je esin ipe adehun, Ọlọhun so bayi pe:
"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ أَوْفُواْ بِالْعُقُودِ أُحِلَّتْ لَكُم بَهِيمَةُ الأَنْعَامِ إِلاَّ مَا يُتْلَى عَلَيْكُمْ غَيْرَ مُحِلِّي الصَّيْدِ وَأَنتُمْ حُرُمٌ إِنَّ اللّهَ يَحْكُمُ مَا يُرِيدُ"
" Eyin onigbagbo ododo, e ma si ka alukawani, A se ni eto fun yin awon eran-osin elese merin (ni jije) ayafi ohun ti a ti ke fun yin, lai rufin ọdẹ sise, nigbati eyin simbe ninu idera ijosin ibewo ile Oluwa, dajudaju Ọlọhun a ma pase ohun ti O ba fe." Suratul Maidah:1.
Isilaamu je esin irora ati pelepele. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-so pe: " pelepe ko ni wa ninu nkankan ayafi ki o se é ni oṣo, a ko si ni yo ọ kuro ninu nkanakan ayafi ki o ba a je." Muslim.
Atipe Isilaamu je esin ife ati ajose. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun ma ba-so pe: " enikankan ninu yin koni di olugbagbo ododo ti yo fi fe fun omo-iya re ohun ti o fe fun ara re." Bukhari ati Muslim.

Ofin shẹriah ti Isilaamu ngba iyanju lati fọn awon ola yi ati awon iwa rere yi ati awon eko yi ka si awujo latara awon ona kan, ninu won;
1 . Ipepe si daradara ati kiko aburu. Ọlọhun ti ola Re ga julo so pe:
" كُنتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَتَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَتُؤْمِنُونَ بِاللّهِ وَلَوْ آمَنَ أَهْلُ الْكِتَابِ لَكَانَ خَيْراً لَّهُم مِّنْهُمُ الْمُؤْمِنُونَ وَأَكْثَرُهُمُ الْفَاسِقُونَ"
" Eyin ni ijo ti o dara julo ti a gbe dide fun awon eniyan, e ma foro awon eniyan sibi iwa rere, e o si ma ko iwa ibaje, e o si gba Ọlọhun gbo niti ododo, ibasepe awon olutele tira gbagbo niti ododo ni, nipaapa iba dara fun won, onigbagbo ododo nbe ninu won, opolopo won ni o si je obileje." Suratu Aal-Imran:110.
2 . Ise isiti ati igbara-eni ni iyaju lori re, ati ise afihan irori ati igbimoran ododo. Ọlọhun so pe:
" وَالْعَصْرِ إِنَّ الْإِنسَانَ لَفِي خُسْرٍ إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَتَوَاصَوْا بِالْحَقِّ وَتَوَاصَوْا بِالصَّبْرِ"
" Mo fi akoko irole bura* Dajudaju eniyan mbe ninu ofo* Ayafi awon onigbagbo ododo ti won si n se ise rere, won si ngba ara won ni iyanju siso ododo, won si gba ara won ni iyanju sise ifarada." Suratul Asr:1-3 .

Ire oluka alaponle yi:
Dajudaju itele esin Isilaamu je ebun Oluwa, ko si eniti o le ni í, ayafi eniti Ọlọhun ba fi se konge, nitorina gbiyanju ki o je okan ninu won, ki o le ba je anfani yi nibi titele esin rere yi, eleyi ti Ọlọhun ko nigba ki a sin pelu nkan miran. Ko mo lori eleyi lasan bikosepe ki o je okan ninu awon olupepe si i, pelu wiwo re si inu esin yi, o pondandan lori re ki o pe eniti ko ti de etigbo re ki o si se alaye aworan rere re fun eniti o se pe aworan ti won ti yipada lo de si etigbo re. Ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á-so pe: ebami jise (fun awon eniyan) koda kosepe aya kan." Bukhari.
Ninu irori mi, dajudaju awon ohun ti a so si inu iwe kekere yi ninu awon iroyin nipa Islam to ki o je ohun ti yoo ta adamo gidi re ni ologo lati mọ nipa esin yi, ti yoo si mu kuro fun o iruju eleyi ti awon oni-iroyin olusini lona tan ka, nigbana o ko ni ri nkankan nipa Isilaamu ayafi ifaseyin, ati iwa akatakiti, tabi awon isesi ti a ko nibi apakan awon musulumi ti won ko mo nkankan nipa Isilaamu ju oruko re lo lere, nipaapa won je okunfa lile awon ti won kii se musulumi jina si Isilaamu, a nse ni adua pe ki Ọlọhun tan imole si inu okan re, ki O si fi ododo mo ọ, ki O si fi o se konge titẹle e, ki O fi ibaje han oniibaje, ki O si fi o se konge jijina si i.

Ifunni ni iro idunnu:
Ire oluka alaponle yi, dajudaju ninu daradara esin Isilaamu ni ki eniti kii se musulumi di musulumi, ti aá si fun ni esan (rere) re ni emeji nitori igbagbo re si ojise re, ati igbagbo ododo re si ohun ti afiran ojise nla Muhammad-ki ike ati ola Ọlọhun ma ba-. Ọlọhun so pe:
" الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِهِ هُمْ بِهِ يُؤْمِنُونَ * وَإِذَا يُتْلَى عَلَيْهِمْ قَالُوا آمَنَّا بِهِ إِنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّنَا إِنَّا كُنَّا مِنْ قَبْلِهِ مُسْلِمِينَ * أُولَئِكَ يُؤْتَوْنَ أَجْرَهُمْ مَرَّتَيْنِ بِمَا صَبَرُوا وَيَدْرَءُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ "
" Awon eniti A fun ni tira siwaju re, won ni igbagbo ododo si i * Atipe nigbati aba nke fun won won yoo so pe: Awa ni igbagbo si i, dajdaju ododo ni i lati odo Oluwa wa, dajudaju awa ti je eniti o ju-owo ju-ese sile fun Ọlọhun siwaju re* Awon wonyi a o fun won ni esan won ni emeji, nitori ifarada won, atipe won fi iwa rere nti buburu seyin, atipe won nna ninu ohun ti A fun won." Suratu Al-Qasas:52-54.
Tun gba iro-idunu keji, ohun nipe dajudaju Ọlọhun yoo pa gbogbo ese ti o ba se siwaju ki o to gba Isilaamu rẹ nitori oro ojise Ọlọhun -ki ike ati ola Ọlọhun maa ba á- to so pe:
" Isilaamu ma npa gbogbo ohun ti o siwaju re (ninu ese)." muslim
Tun gba iro idunnu elẹeketa, ohun nipe Ọlọhun yoo so iwa buburu di rere, eleyi je ajulo oore ti Ọlọhun ma nse fun eniti O ba fe. Ọlọhun ti ola re ga julo so pe:
" وَالَّذِينَ لَا يَدْعُونَ مَعَ اللَّهِ إِلَهاً آخَرَ وَلَا يَقْتُلُونَ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللَّهُ إِلَّا بِالْحَقِّ وَلَا يَزْنُونَ وَمَن يَفْعَلْ ذَلِكَ يَلْقَ أَثَاماً يُضَاعَفْ لَهُ الْعَذَابُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَيَخْلُدْ فِيهِ مُهَاناً إِلَّا مَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ عَمَلاً صَالِحاً فَأُوْلَئِكَ يُبَدِّلُ اللَّهُ سَيِّئَاتِهِمْ حَسَنَاتٍ وَكَانَ اللَّهُ غَفُوراً رَّحِيماً"
" Ati awon eniti kii pe olohun miran pelu Ọlọhun, won kii si pa emi ti Ọlọhun se (pipa re) ni ewo ayafi pelu ododo, won si kii se pansaga, Eniti o ba se eleyi yoo pade idajo ese re.* A o se iya ni ilopo fun u ni ojo igbende, yoo si se gbere ninu re ni eni yepere.* Ayafi eniti o ba ronupiwada ti o si gbagbo ni ododo ti o si se ise rere, awon eniwonyi ni Ọlọhun yoo so ise buburu won di ise rere, Ọlọhun je Alaforijin Alanu." Suratul Furkon: 68-70.
Anfani to rewa ati orire ni eleyi fun eniti o ba lo, bakanna so ara fun lilọ ironupiwada lara, eniti a le pe ni olọgbon ni o nse isiro emi ara re ti o si nsise di eyin iku, atipe eniti a pe ni olẹ eniyan ni eniti o ba ntele ife-inu re ti o wa nfẹ rere lodo Ọlọhun.
Ike Ọlọhun ati ola Re ki o maa ba Annabi wa Muhammad ati awon ara ile re ati awon saabe re. Gbogbo ope ati ẹyin je ti Ọlọhun Oluwa gbogbo agbanla aye.


 
WWW.ISLAMLAND.COM