IPADA SI IPILE

IPADA SI IPILE

IPADA SI IPILE

العودة إلى الأصل بلغة اليوروبا

 

 

 

 

 

‘Abd Ar-Rahmân omo ‘Abd Al-Karîm Ash-Sheha

د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 

 

 

 

Itumo ni ede Yoruba

EUROPEAN ISLAMIC RESEARCH CENTER (EIRC)

المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية

& Abd Ar-Razzaq Isa

Atunto

Ridwanu Allah Murtadho

 

 

WWW.ISLAMLAND.COM

 

 

 

 

 

IPADA SI IPILE

Pelu Oruko Olohun Ajoke Aye, Asake Orun

Gbogbo ope ti Olohun ni, ki ike ati alaafia Olohun maa be fun Anabi wa Muhammad ati awon ara – ile re, ati awon sahabe re.

 

ITISIWAJU

A o maa tenumo alaye agboye Al – Qur’an nipa oro ti Gbogbo eda abara maa n ko airoju nipa a re, oro kan ni ti o je pe kii se asesebere loni yi, bikose pe o ti wa tipe lati igba ti eda abara ti n be, oro kan ni, ti o je pe oun ni ipile gbogbo nnkan, oun si ni ibere re, oun naa ni, oro eda dida, oro igbende, oro Akojo lojo igbende, eleyi ti eni ti yoo gba a gbo ti gba, ti eni ti yoo ko o si ti ko, oun ni oro ti Al – Qur’aan Alaponle ti soro lori ifi iga gbaga awon eniyan nipa atako ti won yoo maa se lori igbende. O wa ninu won awon ti won so pe eegun to kefun nikan ni itumo igbende, bakan naa oro akosile kan ti awon omo n jogun lati owo awon baba won, ti awon baba si n jogun re lati owo baba baba. Olohun ti Ola re ga soro lati salaye eyi:

"قَالُوا أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَئِنَّا لَمَبْعُوثُونَ * لَقَدْ وُعِدْنَا نَحْنُ وَآبَاؤُنَا هَذَا مِن قَبْلُ إِنْ هَذَا إِلاَّ أَسَاطِيرُ الأَوَّلِينَ" (سورة الـمؤمنون 82-83)

"Won wi pe: “Se nigba ti aba ti ku, ti a ti di erupe ati egungun, se won yoo gbe wa dide ni? * Won kuku ti se adehun yii fun awa ati awon baba wa teletele. Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko” (Suurah al – Mu’minnun 82 – 83)

O wa ninu won eni ti o wa jiji awon ti won ti ku siwaju re, ninu awon baba re ati awon baba baba re, ki o le ni igbagbo, o se eleyi niti girimonkai ati atako,

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ هَؤُلاَء لَيَقُولُونَ * إِنْ هِيَ إِلاَّ مَوْتَتُنَا الآولَى وَمَا نَحْنُ بِـمُنشَرِينَ * فَأْتُوا بِآبَائِنَا إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ" (سورة الدخان:33-36)

“Dajudaju awon wonyi n wi pe “Ko si iku kan ayafi iku akoko (ti o pa wa nile aye), Won ko sin ii gbe wa dide* (Bii bee ko), e mu awon baba wa wa ti eyin ba je olododo” (Suurah a-d-Dukaan 33-36)

O wa ninu won, eni ti o woye si pe ipele – ipele ni aye, bakan naa ni o si tun je gbigbeyin awon kan ti won ti lo leyin awon kan, ti o je pe ti awon kan ba lo tan, awon tuntun miiran yoo tun de, pe bayi si ni yio maa lo, laini si igbende, laisi ni si akojo si iwaju Olohun Kankan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَقَالُوا مَا هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا يُهْلِكُنَا إِلَّا الدَّهْرُ وَمَا لَهُمْ بِذَلِكَ مِنْ عِلْمٍ إِنْ هُمْ إِلَّا يَظُنُّونَ (24)" (سورة الـحاثية: 24)

“Won wi pe: “Ko si isemi kan mo bi ko se isemi aye wa yii; a n ku, a si n semi. Atipe ko si nnkan ti n pa wa bi ko se igba. “Won ko si ni imo kan nipa iyen; won ko je kini kan bi ko se alaroso. (Suurah al – Jaathiyah:24)

Alaye oro si maa waye ninu tira kekere yi, nipa alaye ti Al – Qur’an se lori oro yi, eleyi ti o si ba opolo mu ti o si tun dun – un gbo leti tori pe eni ti o ba se aigbagbo si igbende ohun ti o to ju ki a ro si iru eni bee ni pe ko ni le gbagbo pe Adeda wa, eni ti ko ba si gba bibe Adeda gbo won kii ba da imoran ayafi pelu laakaye. Opolopo awon eniyan wonyii ni laakaye re kuku to sona, ti adamo eda re naa si to sona si ibi dida ojulowo nkan mo ati Igbagbo, awon miran yoku si je eni ti laakaye won ko le won kun ni nKankan ayafi iyanjija, ikoja aala ati sisa kuro fun ododo, gege bi awon eniyan Firiaona se se nigba ti Musa mu alaye oro ti o ye yekeyeke wa eleyi ti ododo re daju lemi won, sugbon motomoto, okan giga, titewon aye ju eyikeyi nnkan miran lo loju won, lo mu ki won o maa pe (Anabi Musa) niro, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَجَحَدُوا بِهَا وَاسْتَيْقَنَتْهَا أَنْفُسُهُمْ ظُلْمًا وَعُلُوًّا فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُفْسِدِينَ (14) (سورة النمل: 14)

“Won tako o pelu abosi ati igberaga, emi won si ni amodaju pe ododo ni. nitori naa, woye si bi atubotan awon obileje ti n ri”. (Suurah a-n-Naml: 14)

Awon agbekale oro oni siso papo togunrege, yio pe ipe lo sibi awon eri opolo pipe inu Al – Qur’aan nipa Adedaa ati Eda, ohun ti o se okunfa bibe eda, igbende, rirorun sisele re, ati pipada leyin bibe re. emi n gbero ki n ti awon imo to se anfaani siwaju fun gbogbo eni ti o ba ka (tira) iwe yii. Adua mi fun gbogbo eni ti tira yi ba de owo re ni ki O le teti inu ati tode si ohun ti o n ka, ti o ba gba ohun ti o wa ninu re ti o si ni itelorun pelu e, ope ni fun Olohun, ohun ti a n fe naa ni yen, sugbon ti ko ba ri bee, a je wi pe nkan tuntun ti yio so imo odo re di ilopo ni yio je niyen, fun awon anfaani ti a o ri nibi arojinle lori awon oro inu tira yii, eni ti tira yi ba de owo re, yoo tun le mo okodoro awon oro ti o pamo fun un tabi awon oro ti o de odo re lona odi, tabi lona ti o ruju.

Si maa ri wi pe o n se adua pelu okan ododo ni Gbogbo igba ti o ba ti n ka tira yii bayi:

: Mo pe iwo Olohun Adedaa gbogbo ohun ti n be yii, fi mi mona, tomi si ojuona, to to, to si ni alaafia, Olohun bami mu owo mi lo si ibi ododo, ko si alatileyin Kankan fun mi yato si iwo Olohun” si maa ripe o n ja emi ara a re logun lati le mo ododo ati lati le de aaye ododo, ko da ti o ba je eni ti iro ti gbadun mo tele, ti iwo gan – an si mo lemi re pe o njosin larin ife – inu, ati oju-kokoro, ti o si je pe eda bii ti e naa ni ife –i nu, ti o fi waa di p e o di eru fun ife – inu, ti o ko si mo. Olohun ti Ola re ga so pe:

"وَالَّذِينَ جَاهَدُوا فِينَا لَنَهْدِيَنَّهُمْ سُبُلَنَا وَإِنَّ اللَّهَ لَمَعَ الْمُحْسِنِينَ" (سورة العنكبوت: 69)

“Awon ti won n gbiyanju nipa (esin) wa, dajudaju Awa yoo fi won mo awon ona wa. Atipe dajudaju Olohun wa pelu awon oluse rere" (Suurah Al – ankabut: 69)

O wa ninu iwe " eniyan eni ti a ko mo" ti onimo ise abe kan ati onimo nkan nipa isemi (A surgeon and a’ Biologist) ti o je Faranse, ti won je akosemose alex karil: "Ohun ti ofin faramo ni ki ase iwadii nipa Olohun gege bi o se je pe eniyan maa n di olugbedale nibi igbiyanju re nipa ere idaraya, naa lo se je pe o rorun ki eniyan da Olohun mo latara gbigbe igbadun ju sile ati sise esin, ohun si ni yio fa ifokanbale ati iyonu labala erongba omoniyan, Dajudaju agbara to pamo sinu ati imole emi, ati ife Olohun ati ifokanbale ti koni enu aala, ati awon imole esin, gbogbo re patapata lo je ewa ni paapaa, pelu irufe ipo eyi ti eniyan le maa rankan ni ti paapaa.

Dajudaju eni ti o ba mo Olohun ati akorin awon mejeeji lo maa mo paapaa nkan ni igbeyin latara oju ona aworan to dara lori eniyan. Omoniyan, pelu rire emi re, yoo maa sapa lati mo paapaa nkan ti kole foju ri, fun wi pe o je ododo aladamo to gaju ninu ohun to wa lagbaye. Lori ona a tile ri amuse ero eni, lofa ki omoniyan maa seri emi re si bi awon idanwo to lewu, ko rorun fun eni kankan ki o sapa lati ko di i, eleyi ti pari sibi didarapo emi mo nkan ojulowo ti o ga ju, ti ko ni opin…..!!!

 Opolopo awon eniyan lo ti roro kuro nibi esin pelu imo, ti inu si n dun, ti won n yo, pelu imo ti n be lodo o won, ti awon nnkan kan si han si won kedere, ti won waa lero wi pe, awon ko wa bukata Kankan si esin, nkan ti won mo eleyi le lori ni awon esin atowoda ti o sele laarin bii ogorun mejo odun seyin, agboye esin atowoda yii lo se imo – wiwa ati kiko imo leewo ayafi imo ti o ni i se pelu agbakale soosi (Church) ati awon eko – soosi, ati awon to je mo on, ti o n ri si ohun ti o fa igbedide awon eto omoniyan ati awon awon onimimo nikan pere Atari kikojo awon ijo ijo. Eyi lo si fa ki awon eniyan maa gbe ola fun soosi ati awon eko – ibe, eleyi ti o tako adamo ati laakaye, nipa bayi, lawon eniyan fi sa kuro nibi esin ododo. A ko le bu won fun eleyi – nipa bayi, igunri kuro nibi ododo di ohun ti o fonka. Amo Islaam tako amulo ofin atowoda, nipa bayi o si ilekun fun awon onimimo, o si se awon eniyan lojukokoro wiwa imo, o so esan – rere to wa nibe, o sipe ni irin – ise ijosin eleyi ti a o maa lo fi sunmo Olohun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الَّذِينَ يَعْلَمُونَ وَالَّذِينَ لاَ يَعْلَمُونَ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُوْلُوا الأَلْبَابِ" {الزمر/9}

“So pe: “Nje awon ti won nimo ati awon ti ko nimo dogba bi? Awon onilaakaye nikan ni won n lo isiti”. (Suurah a-z-Zumor: 9)

 Koda, suurot ti o koko so kale fun Ojise Olohun (ki ike ati Ola maa ba a) n pepe lo sibi kika ati mimo ni. Olohun ti Ola Re ga so pe:

" اقْرَأْ بِاسْمِ رَبِّكَ الَّذِي خَلَقَ (1) خَلَقَ الْإِنْسَانَ مِنْ عَلَقٍ (2) اقْرَأْ وَرَبُّكَ الْأَكْرَمُ (3) الَّذِي عَلَّمَ بِالْقَلَمِ (4) عَلَّمَ الْإِنْسَانَ مَا لَمْ يَعْلَمْ (5) " (العلق:1-5)

“Ke (al – Qur’aan) ni oruko Oluwa re, Eni ti O da eda * O da eniyan lati ara eje didi * Ke (e se). Oluwa re ni Alaponle julo, Eni ti o fi imo mo gege, O fi imo ohun ti eniyan ko mo mo o". (Suurha al – Alaq 1- 5)

 Olohun kosi pa Anabi Re lase ki o wa alekun nibi nnkankan laye bikose ibi imo, iyen ri bee, nitori iyi ati ipo giga ti o wa fun imo ninu Islaam. olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَقُل رَّبِّ زِدْنِي عِلْمًا" {طه/114}

“sope: Oluwa mi se alekun imo fun mi” (Suurah Toohaa:114)

 Ki eniyan si tun mo pe, botiwu ki eniyan ni imo, oye ati idagbasoke to, imo won yio si maa je kekeree ni, oye won naa yio si maa ni enu ibi ti o de, won mo nnkankan ni, opolopo nnkan ni won ko tun mo. Eyi ni ohun ti Olohun fi idi re mule pelu oro Re ti o lo bayii:

"وَمَا أُوتِيتُم مِّن الْعِلْمِ إِلاَّ قَلِيلاً" {الإسراء/85}

“won ko si fun yin ninu imo bi kose die” (Suurah al – isro: 85)

 Idagbasoke nibi imo lati ipele kan de omiiran, yio to eniyan sona sibi bibe Olohun ni ti ododo ni, Olohun ti a o maa se afiti gbogbo imo si lodo nigbeyin. Tori pe gbogbo onimimo loni eni ti o mo ju u lo loke re, titi ti a o fi maa pari imo nini sodo Oba Adedaa (Mimo ati Giga ni fun un) Ododo si ni oro Olohun Oba ti o tobi, ti o so pe:

"وَفَوْقَ كُلِّ ذِي عِلْمٍ عَلِيمٌ" {يوسف/76}

“olumo nbe loke gbogbo onimo kooka” (Suurah Al – Yusuff: 76)

 Onimo kaaril so bayi ninu iwe re, ti o pe ni Dhaalikal Maj’huul” “O ti di o n ti o ye ni yekeyeke to, fun wi pe idagbasoke gbogbo imo to je imo tomoniyan, ko le to fun gbigbo bukaata wa. Ni soki, imo wa nipa ara wa g an – an, ko le ye tabi ki o gbo ni ohun ti yio maa wa ni ipo asese bere”. O tun so pe: “A ko lagbara lati ni imo de ibi ki a mo awon asiri eda omoniyan pelu sise amulo iru ogbon ti a maa n lo fun awon nnkan miiran ti ki i se nipa eda omoniyan, koda, ikagara ti o ga, ti o si tobi, ni pe eko wa ti a fe ko lati ara oborogidi ara ti emi ti kuro nibe, pada n di ohun ti a ko gbadun daadaa bii igbadun eyi ti a maa n ri latara alaaye eniyan.

            Bayi gele ni awon imo agbelero se n je ohun ti o ni enu aala ibi ti o de nipa imona eda, ati nipa ona abayo isoro omoniyan yii. Amosa awon kan n lo bee pelu bi o se kuna die yii, nitori pe won fe tako ise imisi, won fe pe awon Ojise ni iro, won fe ko esin sile, won si fe tan igunri kuro nibi ododo kale.

            Fifonkale ibaje nibi olaju ti awon ara iwo oorun gbe wa (Western civilization) ati ibaje ti won se fun awon iwa abiyi eleyi ti o ti ko iparun ba awon opolop idile. Bakannaa, fifokanle ti awon aisan to ni i se pelu awuju ti fonkale, je ohun ti o ni ewu, ti o si n ba afefe alaafia awujo je, laelae olaju awon ara iwo oorun ko le mu inira yii kuro, Ayafi ki a pada si ohun ti awon Ojise Olohun mu wa (Ki ike ati Ola maa ba won)

            Ni pataki ju lo, ise ti a fi ran Anabi Muhammad (Ki Ike ati Ola maa ba a) ohun ni se to gbeyin, ti o je o n ti a fi pa awon ise to gbawaju re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلاَّ رَحْمَةً لِّلْعَالَمِينَ" {الأنبياء/107}

“Awa ko si fi ise imisi ran o bi ko se pe ki o le je ike fun gbogbo eda” (Suurah Al - Anbiyya: 107)

 

 

ALAYE AWON NNKAN KAN LEKUN – UN RERE

  • Awon akole idanilekoo ti a tenu mo ninu iwe kekere yii, je awon akole kan ti a se idanilekoo re ni kukuru pupo, won kan je awon atona ati itokasi ni, ohun ti o fa eyi ni pe a n beru fifagun iwe yi fun awon eni aponle ti yoo maa ka. Eni ti o ba waa fe afikun, tabi ti o fe mo ekunrere alaye nipa awon die ninu akole idanilekoo, ti o ri wi pe agboye alaye yii le mu ki ilapa ba ero okan oun, ope ni fun Olohun, Oro ti o rorun daadaa ni eyi. Ki iru eni yii maa se iwadii ibi ti awon ile – ise ti Islaam gbe kale, ti o si je ile – ise kan tio se gbe ara le. Tabi ki o wa ona a ti o sunmo (Islamic Centre) ile – ise Islaam kan, eleyi ti o si tanka kaakiri opolopo orile – ede lagbaye.
  • Ofin ati Ilana ofin ni Islaam, o si je ohun ti o feserinle, nigba ti awon Musulumi je eni ti yoo maa lo ofin naa. O se e se ki o ri ninu awon Musulumi, eni ti o n puro, ti o n se awon ese to po, eleyi ti won ti ko fun un lati se, ti ofin esin si ti ko wa pe ki a sora fun. Bakannaa gbogbo awon nnkan wonyi naa lo wa ninu awon esin ati awon ojuona miran. Eleyi fi n ye wa pe, awon alafo ti n be nibi amulo ofin esin lodo awon Musulumi kan ki i se alafo ti a maa so pe ofin esin loni i funra a re, ko leto ki lilupo maa sele laarin ofin esin ati amulo ofin esin, ko si leto ki a maa mu idajo Islaam wa ni ohun ti a mopa lori awon isesi awon Musulumi kan, eleyi ti o ni abuje – nje – ku, ti o si jinnna si ohun ti o ba amulo ilana ati eko ofin esin mu.
  • Abala awon ofin esin atorunwa kan maa n pari ibi ti omiran ku si ni, Ipile kansoso ni gbogbo re, ohun naa si ni (At – tawhid) (mimu Olohun lokan soso). Awon ofin esin won si yato si ara won (Awon tira sanmo ni) Suhufi Ibrahim, Az – Zabuur, At-Taorah, Al – Injiil, won si fi Al – Qur’aan pari re. al – Qur’aan si ni iwe ofin esin Olohun ti o keyin, ti o si pari awon ibi ti awon ofin esin sekusi, ko si leto ki a gboye sipe abuku n be lara awon iwe ofin esin miiran ti o je iwe ofin to wa lati sannmo, tori wipe eni ti o ba fi abuku kan iwe ofin kan ninu awon ofin miiran to wa lati sanmo ti di (keferi) alaigbagbo, o si kuro ninu Islaam. Olohun ti Ola Re ga so pe:

" قُولُوا آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنْزِلَ إِلَيْنَا وَمَا أُنْزِلَ إِلَى إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَمَا أُوتِيَ مُوسَى وَعِيسَى وَمَا أُوتِيَ النَّبِيُّونَ مِنْ رَبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْهُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ (136)" {البقرة/136}

“E so pe “A ni igbagbo ododo ninu Allahu ati ohun ti won sokale fun wa ati ohun ti won sokale fun (awon Anabi) Ibrohiim ati Ismahil, ati Ishaq, ati Yahqub, ati awon asbaat, (awon arodomo yahqub) ati ohun ti won fun Musa, ati Isa, ati ohun ti won fun awon anobi lati odo Oluwa won, a o se onpinya larin enikankan ninu won, olugbafa si ni wa fun un” (Suurah Al – Bakhora: 136)

 Gbogbo ofin esin lo je pe o pe perepere ni igba ti tie ti a so o kale, o si wa ni ibamu si ohun ti awon ti a firanse si nilo lasiko yen. Ojise Olohun (Ki ike ati Ola maa ba a) salaye itumo oro yi ni ti paapaa. “Apejuwe mi si awon Anabi Olohun to siwaju mi waye, da gege bii okunrin kan ti o kole, ti o si se loso daadaa, ayafi aye biriki kan lara ogiri, awon eniyan ba bere si ni maa rokiri ka ile naa, won si bere sii ni i se enmo, won n so pe: “Kilode ti o fi fi alafo biriki kan yi sile n tie? Dahun pe: emi ni biriki kan to seku naa, emi si ni ikeyin awon Anabi Olohun. Bukoriy, Muslim, Ahmad, Ibn Hibaan ati Tirimidhi lo gba a wa.

            Nipa bayi, awon esin to wa lati sannmo, da gege bi ile ti gbogbo awon Anabi Olohun patapata kopa nibi kiko re, gbogbo Anabi ti won gbe dide lo gbe biriki kan si ile naa ti o fi pari, ti kosi ku nnkankan nibe ayafi aye biriki kan pere ti yio fi pe pari. Olohun gbe Anabi Re ti i se Muhammad (Ki ike ati Ola maa ba a) ga, esin re, ati ofin esin re si ni biriki ti ile naa yio fi pari ti yio si fi pe perepere.

  • Niti ibamu si ipo ti esin wa lagbaye laiyo ibikankan sile, a o ri pe Islaam nikan ni esin ti won n gbogun ti yato si awon esin ati awon ojuona miiran. Wa asiko ti o fi le ronu ti o si fi le se iwadi daadaa fun ara a re, (ki o wa beere pe) kinni o fa imulota yii, o maa ri wi pe, ohun ti o se okunfa ni bi o se je pe oun ni esin ti o so omoniyan di eni ti n sin Eledaa won, sugbon awon esin yoku, won n so eda abara kan di ki o maa sin eda abara miiran. eleyi je abala kan. Abala keji si tun ni pe (Islaam) je esin kan ti ko fi aye gba abosi, eru, ati tenbelekun ote. Olohun ti Ola Re ga so bayi ninu Hadith mimo: A gba oro yii wa lati odo Abu Dhar ara ile al – Ghifar; ki Olohun yo’nu si i, o wi pe Anabi; ike ati Ola Olohun ki o maa baa, ninu awon egba oro ti o gba wa lati odo Oluwa re, Oba Alagbara ati Alaponle, wi bayii pe: “Eyin erusin Mi! mo se abosi ni eewo fun ‘ra Mi, Mo si tun se e ni eewo l’aarin yin, nitori naa e ko gbodo se abosi (si) ara yin”. Muslim ni o gba a wa

Bakan naa (Islaam) ko yonu si motomoto ati okan giga. Olohun ti Ola re ga so pe:

"وَلاَ تُصَعِّرْ خَدَّكَ لِلنَّاسِ وَلاَ تَمْشِ فِي الأَرْضِ مَرَحًا إِنَّ اللَّهَ لاَ يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ {لقمان/18} وَاقْصِدْ فِي مَشْيِكَ وَاغْضُضْ مِن صَوْتِكَ إِنَّ أَنكَرَ الأَصْوَاتِ لَصَوْتُ الْحَمِيرِ" {لقمان/19}

“Ma se gbe eeke re kuro ni odo eniyan ni ti igberaga. Ma si se rin ni ori ile pelu faari. Dajudaju Olohun ko feran gbogbo onigbeeraga, onifaari * Je ki irin ese re wa ni iwontun – wonsi, ki o si re ohun re nile. Dajudaju ohun ti o buru ju lo ni ohun ketekete” (Suurah Luqmoon: 18 – 19)

 Kosi tun yonu si ima je owo awon eniyan lona ibaje. Olohun ti Ola re ga so pe:

" وَلَا تَأْكُلُوا أَمْوَالَكُمْ بَيْنَكُمْ بِالْبَاطِلِ وَتُدْلُوا بِهَا إِلَى الْحُكَّامِ لِتَأْكُلُوا فَرِيقًا مِنْ أَمْوَالِ النَّاسِ بِالْإِثْمِ وَأَنْتُمْ تَعْلَمُونَ (188) " {البقرة/188}

“Eyinko gbodo fi eru je dukia yin laarin arayin. Eyin ko si gbodo gbe dukia lo ba awon adajo, ki e le je apakan dukia awon eniyan lonan ese, be sini e mo bee” (Suurah Bahkhoraa: 188)

 Kosi tun yonu si fifi eto awon eniyan dun won, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تَبْخَسُواْ النَّاسَ أَشْيَاءهُمْ" {الأعراف/85}

“E ma se din nnkan awon eniyan ku.” (Suurah – Al a’raaf: 85)

Ko si yonu si ki alagbara maa yepere ole, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"فَأَمَّا الْيَتِيمَ فَلاَ تَقْهَرْ * وَأَمَّا السَّائِلَ فَلاَ تَنْهَر"{الضحى 9/10}

 “Nitori naa, ni ti omo – orukan, ma se je gaba (le e lori) * Ni ti alagbe, ma si se jagbe (mo on)” (Suuratul – Al-dhuah: 9 - 10)

 Kosi yonu si ki oloro maa je eto Alaini. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ يَحْسَبَنَّ الَّذِين يَبْخَلُونَ بِـمَآ ءَاتَاهُمُ اللهُ مِنْ فَضْلِهِ، هُوَ خَيرًا لَّـهَّم بَلْ هُوَ شَرٌّ لَّـهُمْ سَيُطَؤُقُونَ مَا بَـخَلُوا بِه يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَللهِ مِيرَاثُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَاللهُ بِـمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ" {سورة آل عمران 180)

“Ki awon tin sahun pelu ohun ti Olohun fun won ninu oore – ajulo Re ma se lero pe oore ni fun won. Rara, aburu ni fun won. A o fi ohun ti won fi sahun de won lorun ni Ojo Ajinde. Ti Olohun si ni ogun awon sanmo ati ile. Olohun ni Olumo – ikoko ohun ti e n se nise” (Suurah aali – Imroon: 180)

 Kosi yonu si ki a maa mu awon eniyan sin nitori pe a maa nse sababi bibiya bukata fun won. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَأَحْسِنُوَاْ إِنَّ اللّهَ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ" {البقرة/195}

 “E se rere, Dajudaju Olohun nife awon oluse rere” (Suuratul – Al – Bahoral: 195)

 Kosi yonu si ibaje ati sise ibaje, yala fun enikookan tabi fun ijo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تُفْسِدُواْ فِي الأَرْضِ بَعْدَ إِصْلاَحِهَا ذَلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ" {الأعراف/85}

“Esi ma se ba ileje leyin atunse re. iyen ni o dara fun yin ti e ba je onigbagbo ododo” (Suurah – Al – AR – Rorf: 85)

 Mo fe daju ibeere kan ko gbogbo eniyan toni laakaye sinu: se esin ti awon ofin ti o gbe duro ri bayii ye ki won o maa gbogun ti, ki won o si maa mu un lota?

 Esin Islaam yi je anfaani nla fun eda abara gege bi Ojise Olohun (Ki ike ati Ola maa ba a) to so pe: “Eni ti Olohun feran julo ni eni ti o n se anfaani fun awon eniyan julo, bakan naa ise ti Olohun feran julo ni idunnu kan ti eniyan ko sokan Musulumi, tabi pe o ba a gbe ibanuje kan kuro, tabi pe o ba a san gbese tabi pe o ba a le ebi lo”. (Daaru kotni Ibn lo gba a wa). Al – Al – baaniy si fi nini alaafia re rinle ninu Sohihul – jaamiu 3,289, As – Sohihat 426.

            Bakan naa ife gbogbo eda abara lo tun je, Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: "Enikan kan ko le tii di Olugbagbo ododo titi ti yoo fi maa fe fun omo – iya re iru ohun ti o n fe fun ara a re". Muttafak Alaei

            Alaafia Olohun ki o maa je ti eni ti o ba gba a (Islaam) ogun ko si maa je ti eni ti o ba gbogun ti i. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لاَ يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ أَن تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ * إِنَّمَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ قَاتَلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَأَخْرَجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ وَظَاهَرُوا عَلَى إِخْرَاجِكُمْ أَن تَوَلَّوْهُمْ وَمَن يَتَوَلَّهُمْ فَأُوْلَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ" {الممتحنة8/9}

Olohun ko ko fun yin nipa awon ti ko gbe ogun to yin ninu esin, ti won ko si leyin jade kuro ninu ilu yin, pe ki ese daadaa si won, ki e si se deede si won. Dajudaju Olohun feran awon oluse dede. Ohun ti Olohun ko fun yin ni nipa awon ti won gbogun ti yinninu esin, ti won si le yin jade kuro ninu ilu yin, ti won tun se iranlowo (fun awon ota yin) ati leyin jade, ohun nipe (o ko fun yin) lati mu won ni ore. Enikeni ti o ba mu won ni ore, awon won yen ni awon alabosi” (Suurah Al – mumtahinan: 8-9)

Dajudaju imaa si kuro lati ibi esin kan lo si ibi omiran oro toye yekeyeke nipa e ipo ti aye wa ni ye. A ti ri ninu awon Yahuudi awon ti o se pe awon ni won di esin won mu sinsin julo ninu awon eniyan eni ti n kuro lati inu esin re lo sinu esin miiran, a si ti ri opolopo awon Nasoroh awon ti won koni ayo okan pelu esin won, ti won si pada bere ise iwadii niyin lohun lori bawo lawon se fe re ongbe emi, ti awon si se fe ri ibale – okan, awon elesin Al – Hunduus, ati awon elesin (Budisin) Buudhiyuun ati awon elesin (Budisim) Buudhiyuun ati awon elsin Al – siikha ti won je awon ti won mo esin won lori irori ara a won, ati awon akosile ti won ba laye nikan ti won mu esin Nasooroh ni esin ti awon o maa sin, esin Nasoorh ti awon to n se gan – an n fi sile pada fun airi itelorun won nibe. Yato si esin Islaam, eleyi ti o se pe eni ti o ba ti wonu e, o won pupo ki a ripe yoo tun pada jade ninu e. bi ko se pe ohun ti won n so nipa re kaakiri aye ni pe, ohun ni esin ti o nn yara tanka julo lagbaye, esin kan ni, ti o je pe won fi owo ati dukia, ati awon eniyan nlanla gbogun ti i, lati ripe won seri awon eniyan kuro nibe, ati lati da titanka re yii duro. Sugbon to je pe tohun ti bee naa, gbogbo igbiyan won n jasi pabo ni. won wa pada dabi eni ti o mu ogunna ju sinu ina kosi nnkan ti yio sele si i bi ko se pe ki o di ina ti yio jo lo. Iyen ri bee tori pe esin Olohun ti Olohun se adehun pe Oun yoo maa so ti oun yoo si maa ranse ni Islaam. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يُرِيدُونَ أَن يُطْفِؤُواْ نُورَ اللّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَيَأْبَى اللّهُ إِلاَّ أَن يُتِمَّ نُورَهُ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ" {التوبة/32}

 “Won se lati fi enu won pa imole (esin) Olohun, Olohun si ko (fun won) ayafi ki O pe imole (esin) Re, awon alaigbagbo ibaa korira (re) (Suratul Taobah: 32)

 Awon wonyi ni awon to se pe won ti bere si ni si kuro nibi awon esin won lo si bi awon esin miiran, fun ai ni itelorun pelu esin won. Mo n doju ipepe mi ko won bayi ki won fi le mo esin ti o pe, ti o ye lati sesa, ti i se esin Islaam, esin ododo, ti ko tako laakaye, ti kosi tako adamo omoniyan.

 

 

TAANI OLOHUN?

            Boya ki n to so itumo Olohun, Oba ti n toju gbogbo eda, ki a koko te n pele mo oro opolo ti Olohun fun omoniyan, pelu wiwoye si abala awon nnkan ti o rorun fun opolo lati maa se, ati bi o se je pe o loju ohun ti o le se, ti Olohun ti tori i re da a, ti omoniyan si fi da yato si awon eda miiran, ti n be laye, ki won fi le da Olohun mo latari ironu jinle nipa awon eda Olohun, ati bi awon eda se n lo laakaye. Bi iru ilo laakaye si nnkan ti yio mu anfaani wa fun won lori esin won ati ni ile aye won. Fun apeere. Emi ti n sise ninu ara, ati ara ti ko lemi ti o n di oborogidi ara, a mo kuku ya ole o, a o ni agbara lati le fi awon eya ara ti a fi n da nnkan mo mo nnkankan ti emi ba ti kuro lara. Ara yen koni le ri, koni le gbo oorun, koni le gba nnkan kan mu, kosi ni le gbo nnkan kan, bee si ni laakaye wa kagara lati mo emi ati lati mo papaa ohun ti n je emi, enu wi pe a gba bibe re gbo, pe eda kan ninu awon eda Olohun ni i se kin lo wa lero nipa eni ti o da emi, ti o je ki emi maa be? Tori idi eyi, nigba ti won bi Ojise Olohun leere nipa emi, lati odo Olohun ti Ola Re ga ni idahun ti wa bayii:

"وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الرُّوحِ قُلِ الرُّوحُ مِنْ أَمْرِ رَبِّي وَمَا أُوتِيتُم مِّن الْعِلْمِ إِلاَّ قَلِيلاً" {الإسراء/85}

 “Won n bi o leere nipa emi sope emi n be niu ase Oluwa mi. awa ko si fun yin ninu imo bi ko se die” (Suratul Al – Israhi: 85)

 Seyyid Qutbu (Ki Olohun ba ni ke e) so pe: Ilana ti Al – Qur’aan rin ohun ni ilana to rinle julo – ohun ni kii eniyan maa dahun ohun ti o wa bukata si, ati ohun ti imo re le kapa idamo re de ogongo gege bi eda abara. Nipa bayi, agbara opolo ti Olohun fun laakaey ti O fi ta awon eda abara lore, ki i fe se wahala nibi ohun ti ko le ni abajade tabi ki o so eso, ati pe nibi ohun ti kosi ninu ise ti o le se, koni lagbara ati se e. sugbon itosona maa n be fun opolo omoniyan lati fi se owo enu ohun ti a la kale fun un, sugbon nibi ohun ti a la kale fun pe ki o le se, koni kagara sise re. nibi si sapa lori ohun ti laakaye ko le mo, koye ki a da ara wa laamu lori e, tori pe koni awon ategun ohun ti o fi le da nnkan nan mo.

            Nigba ti oro bari bayi nipa awon eda Olohun bawo wa ni o lero pe yio ri nipa Oba Adedaa, ati sise ise dida paapaa Olohun mo. Eleyi wa ninu ohun ti oye laakaye eda abara ko le gbe, laakaye eda kole gbe imo paapaa bi Olohun se ri. Tori naa ere lasan ni yio tumo si, tori pe eda ni laakaye o si ni enu aala ibi ti ko lagbara lati koja re, tori pe oro kan ti Olohun ti da duro si enu ibi ti o le mo mo pelu gbolohun Re yi.

"وَلاَ يُحِيطُونَ بِهِ عِلْمًا" {طه/110}

“(Awon Eda) ko si le ni mo amotan nipa Re” (Suuratul – Al – Tooha: 110)

Olohun ti Ola Re ga tun so pe:

"لَيْسَ كَمِثْلِهِ شَيْءٌ وَهُوَ السَّمِيعُ البَصِيرُ" {الشورى/11}

“Ko si kini kan bi iru re. Oun si ni Olugbo       Oluri” (Suuratul – Surooo: 11)

Olohun ti Ola Re ga tun so pe:

"لاَّ تُدْرِكُهُ الأَبْصَارُ وَهُوَ يُدْرِكُ الأَبْصَارَ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ" {الأنعام/103}

“Awon oju (eda) ko le ka Olohun (nipa tito bi Re) O si rogba yi awon oju ka. Oun si ni Alaanu, Olumo ikoko” (Suratul Al – nham: 103)

 Apejuwe eni ti o ba fi opolo re ko airoju nipa oro yi da gege bi eni ti o gbe eru apo eru ti o wuwo marun sinu oko ti kole gbe ju apo kan lo. Kosi iyemeji nibi wi pe eyi maa je okunfa ki o ma le ni agbara ati le gbera, bakan naa o si le ko iparun ba oko naa. Bayi gele ni laakaye eda abara ri nibi ironu nipa paapaa Olohun tabi nipa ohun ti o wa leyin nnkan ti o pamo, ti o se pe eniyan ko le daa mo ayafi ni ipase ohun ti awon Ojise – Olohun ba so.

            Awon ara Yamman ti beere lowo Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) pe: Awa wa ba o, lati bi o nipa oro yi. Ojise – Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) dahun pe: "Olohun je eni ti o n be, ko si si elomiran to n be yato si Olohun"

 

 

NIBO NI OLOHUN WA?

            Dajudaju Olohun ti o ga julo ti o tobi julo, n be ni oke, oke Al – Arashi Re, loke sanmo mejeeje, sugbon awon kan lara awon olutopinpin maa n beere pe: nibo ni Olohun wa, pelu erongba pe aaye kan pato ninu aye yi (ni ibi ti Olohun wa), awa wa n so pe: Olohun ti o ga julo, ti o si tobi julo ni eledaa aaye ati igba, beesi ni eni ti o da aaye ati igba aaye kan kole gba a, igba kan kosi le da ejo le lori, oun ni eni ti n be, ti nnkankan kobe siwaju Re tabi leyin Re, kosi si elomiran loke paapaa bibe re, oun ni eni ti o gunwa sori Al – Arashi re, kosi si eni ti o sunmo eniyan pelu imo Re to to Olohun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"هُوَ الأَوَّلُ وَالآخِرُ وَالظَّاهِرُ وَالْبَاطِنُ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ" {الحديد/3}

 “Oun ni Akoko ati Ikeyin (pelu ami bibe Re) O si pamo (fun gbogbo oju nile aye). Oun ni onimo nipa gbogbo nnkan.” (Suratul Al – Hadeede:3)

 A ko kapa lati mo awon iroyin Olohun tan ninu tira kekere yi, ti a se ni sokisoki, sugbon a o so die ninu awon iroyin Olohun Adedaa aye yii, ninu awon oro ti o n bo wonyii:

  • Olohn ni Oba Okansoso, ti koni orogun ti kosi ni Akegbe tabi Alafiwe nibi eda dida, titoju eda ati nibi awon iroyin Re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ * اللَّهُ الصَّمَدُ * لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ * وَلَمْ يَكُن لَّهُ كُفُوًا أَحَدٌ {الإخلاص 1/4}

So pe: “Oun ni Olohun, Okan soso * Olohun ni Eni ti edani bukata si, ti Oun ko si ni bukata kan kan si won * Ko bimo. Won ko si bi, ko si ni alafiwe kankan” (Suurathl a-n-Naas: 1 – 4)

  • OUN ni Oba Alaaye gbere ti koni ku. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"هُوَ الْحَيُّ لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ فَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ" {غافر/65}

“Oun ni alaaye ko si Olohun ti ijosin tosi afi Oun. Nitori naa, e pe e (kii eje) Olusafomo – esin fun un. Gbogbo ope nje ti Olorun Oluwa gbogbo eda”

(Suurah Gaofir: 65)

  •  Gbogbo nkan miran toyato si ni o je pe titan ni apadasi won ma an je. Olohun ti Ola re ga so pe:

"كُلُّ مَنْ عَلَيْهَا فَانٍ * وَيَبْقَى وَجْهُ رَبِّكَ ذُو الْجَلاَلِ وَالإِكْرَامِ {الرحمن/27}

“Gbogbo eniti o wa lori ile ni o maa tan * O si ma seku oju Oluwa Re, Atobi, Alaponle” (Surath Ar Rahom: 26 – 27)

  • Olohun ni eni ti o da duro fun ra a re, ti o ro oro tayo kofi ara ti eda, ko wa bukata si eni ti yoo gbe duro, OUN ni eni ti o n gbe elomiran duro, elomira Kankan kole duro ayafi pelu agbara Olohun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"اللّهُ لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لاَ تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلاَ نَوْمٌ لَّهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الأَرْضِ مَن ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلاَّ بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلاَ يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِّنْ عِلْمِهِ إِلاَّ بِمَا شَاء وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ وَلاَ يَؤُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ {البقرة/255}

“Olorun, ko si Oloun kan ti Ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuto eda. Oogbe kita A, ati pe oorun ki i kun Un. TiRe ni ohunkohun ti n be ninu awon sanmo ati ohukohun ti n be ninu ile. Ta ni eni ti o le sipe lodo Re bi ko je pelu ase Re? o mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be leyin won. Won ko si ni imo amotan nipa kini kan ninu imo Re afi ohun ti O ba fe (fi mo won). Aga Re gbaaye ju awon sanmo ati ile lo. Siso sanmo ati ile ko si da A lagara. O ga, O tobi”. (Suurath al – Baqoah: 255)

  • Olohun ni ojogbon ninu awon ise e re ati oro Re ati ipebubu Re, nipa bayi, o gbe gbogbo nnkan si aaye re pelu ogbon Re ati deede re, Oludajo loje fun eda Re, oni mimo si ni nibi didari oro awon eda si bi ohun ti o maa je atunse fun won. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"هُوَ الْقَاهِرُ فَوْقَ عِبَادِهِ وَهُوَ الْحَكِيمُ الْخَبِيرُ" {الأنعام/18}

“Oun si ni olubori awon erusin Re oun ni Ologbon Olumo – Ikoko” (Suurah Aniaam: 18)

  • Olohun ni Olugbo, Oluriran, ti nnkan ko pamo fun un bi o ti wu ki o mo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَهُ مَا سَكَنَ فِي اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ" {الأنعام/13}

“TiRe ni ohukohun ti n be ninu oru ati osan. Oun si ni Olugbo Olumo”

(Surrah Aniaam: 13)

  • Olohun ni Alabgara ti kosi nnkan ni ile ati ni sanmo to le ko agara ba a. olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَيْنَ مَا تَكُونُواْ يَأْتِ بِكُمُ اللّهُ جَمِيعًا إِنَّ اللّهَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ" {البقرة/148}

“Ibikibi ti e ba wa, Olohun yo mu gbogbo yin wa (ni Ojo Ajinde) Dajudaju Alagbara ni Olohun lori gbogbo nnkan” (Surrah Al – Bakhora: 148)

  • Olohun ni Olumo gbogbo nnkan, imo re si rokirika gbogbo nnkan, aimo kosi siwaju imo Re, bakannaa igbagbe kosi fun un, O mo ero ti o pamo sinu okan, O n lo mo gbogbo ohun ti o ti nbe, ati gbogbo ohun ti n be lowo, ati gbogbo ohun ti yio maa be ati gbogbo nnkan ti ko ni ma abe. OUN lo si ni ka pe n be, bawo lo se n be. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا يَعْزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثْقَالِ ذَرَّةٍ فِي الأَرْضِ وَلاَ فِي السَّمَاء وَلاَ أَصْغَرَ مِن ذَلِكَ وَلا أَكْبَرَ إِلاَّ فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ" {يونس/61}

“Kosi nkan ti o pamo fun Oluwa Re, bi o mo ni ondiwon omo ina igun ninu ile ati ninu sanmo, ki o tun kere ju iyen lo tabi ki o tobi julo (ko niii maa be) afi ki o ti wa ninu akosile to yanju” (Suuratul – Yunus: 61)

  • Olohun ni Olupese: - Ije – imu fun gbogbo eda Re, ti o nmu gbogbo nnkan ti eda n fe ninu isemi re wa ba a.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا مِن دَآبَّةٍ فِي الأَرْضِ إِلاَّ عَلَى اللّهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ" {هود/6}

“Ko si eda kan ti o wa ni ori ile afi ki arisiki re wa baa lati odo Olohun, O mo ibugbe re ati ibusun re, Gbogbo re ti wa ninu akosile ti o han kedere” (Suuratul Huud: 6)

Olohun ni Alagbara lori siso nnkan di alaaye ati oku, igbende ati Akojo ojo igbende. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلِ اللَّهُ يُحْيِيكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يَجْمَعُكُمْ إِلَى يَوْمِ الْقِيَامَةِ لاَ رَيبَ فِيهِ وَلَكِنَّ أَكَثَرَ النَّاسِ لاَ يَعْلَمُونَ" {الجاثية/26}

“Sope: “Olohun ni O n so yin di alaaye. Leyin naa o maa so yin di oku leyin na O ma se ako yin ni ajo Ajinde ti ko si iyemeji ninu re, sugbon opolopo eniyan ni komo” (Suurah Al – Jatheeya: 26)

 

 

Oba yi ni Olohun wa:

- Alaaanu julo ti O feran awon ti o ba maa n se aanu ninu awon eru Re. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: “E maa saanu awon to n be lori ile, awon to wa ninu sanmo na ayoo maa saanu eyin naa. Sohih Tirmidhi.

  • Oba Alaforijin to feran awon ti o maa n sumojukuro fun awon elomiran. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"خُذِ الْعَفْوَ وَأْمُرْ بِالْعُرْفِ وَأَعْرِضْ عَنِ الْجَاهِلِينَ" {الأعراف/199}

“Se amojukoro pase sise rere, kosi seri kuro ni odo awon alaimokan”

(Suratul Alaraaf: 199)

Oba Olore ti O feran awon to maa n tore ninu awon eru Re: Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: “Dajudaju Oba Olore ni Olohun, ti o si feran awon ti o maa n tore ninu awon erusin Re. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) sope: "Dajudaju Oba Olopo – ore ni Olohun, O feran ore tita, o si tun feran awon iwa to dara ti o je iwa. Alapon le, o si korira awon iwa iyepere, iwa aburu.

  •  
  • Oba Onipelepele to feran awon to maa n se pelepele. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) sope: " Dajudaju Oba Onipelepele ni Olohun, o si feran pelepele sise, a si maa san esan nitori pelepele sise, iru esan ti ko le san fun eni ti o le koko mo awon eniyan, bakan naa iru esan ti ko ni i san eniyan lori nnkan miiran yato si sise pelepele. (Muslim ati Ibn Hibaan lo gba a wa).
  • Oba Olubasiri ni Olohun, o si feran iwa imaa basiri laarin awon erusin Re. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: "Eru kan koni bo eru kan lasiri nile aye, ayafi ki Olohun bo iru eni bee naa lasiri lojo igbende. (Muslim ati Ahmad lo gba a wa).
  • Oba Arewa ni Olohun, o si feran ewa, o feran imora, ati imototo latodo awon erusin Re. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: "Oba Arewa ni Olohu, O si feran ewa. (Sohiih Muslim).
  • Oba Olojuti ni Olohun, O feran riri ojuti laarin awon erusin Re. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: "Dajudaju Olohun to ga, to gbon – n gbon je Oba onisuuru, Olojuti, Olubasiri ti O feran itiju, ibo – asiri, ti enikookan yin ba ti fe e we, ko maa ri wi pe oun bo ihooho ara oun". (o ni alaaafia, Ahmad, Abu Dawu ati An – Nasaah lo gba a wa).

 

 

 

AWON ERI OLOPOLO LORI BIBE OLOHUN

            Ikan lara awon to ti gunri kuro loju ona Islaam beere lowo Sheikh Ahmad Deedaat ki Olohun ba ni ke pe: Bawo ni yio se ri lara a re, ti o ba ku, to wa pada han si o wi pe iro ni n je isemi ikeyin? O si dahun pe: kosi ohun to buru nigba ti o ba ku, ti o to ki o pada han si o pe otito ni. boya idahun le to fun onilaakaye, ki emi re fi le mo ohun ti o ye, ki o si fi bere si ni maa wa isora fun ohun ti o le ba pade niwaju re. Tori pe, onilaakaye ni eni ti o maa n se isoro ara a re, ti o si maa n sise lati gbaradi fun isemi eyin iku. Boya eri to feserinle ju lori bibe Olohun si ni eri nkan ti a le foju ri eleyi ti enikookan kole lagbara lati tako. Nipa bayi, bibe gbogbo awon nnkan to wa laye letoleto ti eto re je ohun ti n yani lenu, bii bibe ile, sanmo, didaa gbogbo nnkan ti o wa ninu sanmo ati ile bii awon eda abara, eda eranko, kokoro, okuta, igi, awon irawo, ooru, osupa, awon ibudo, awon akeromodo, ati awon nnkan miiran, ti gbogbo won si n rin lori eto ti a la kale fun won, ti o se pe ti nnkan ba sofo ninu eto yii, o ba tii ri isemi. Taani eniti o n mu ki gbogbo re maa be, ti o si seto to danmoran ti o n je iyanu nla yii? Irori orisi meta naa la o maa ro nipa eyi, kope merin.

AKOOKO: ki Ile – aye yii pelu eto re ti o yani lenu, ti o si teni lorun, ti o si gbooro fun wi pe awon agbaye orisirisi lo wa nibe, je ohun ti a nri latodo ara a re. iru irori bayii, ti di ohun ti a gba danu, ohun ibaje lati ipile aye, tori pe Gbogbo nnkan ti n be, lo gbodo ni ohun ti n mu be, gbogbo eda lo si gbodo ni Adedaa gbogbo (Sababi) Okunfa, lo si gbodo ni (Musabib) Olusokunfa.

IKEJI: Ki a lero pe nnkan kan lo mu ki aye yi maa be, nnkan yii si se se ko je pe o wa nile aye. Oro yii je oro ti o se e maa so, ti ko si se gba wole ninu laakaye, tori pe nnkan ko le da nnkan bii re.

IKETA: Ki a lero pe ile aye yii, pelu gbogbo n towa nibe, Eledaa kan lo mu be, lo si tun da a pelu. Eledaa yii si ti jade kuro ninu aye. Eleyii ni irori ti o ba laakaye mu, ti ohun ti n sele naa si gba sododo, oun naa si ni OLOHUN Oba Olutoju gbogbo eda. Eyi ni ohun ti gbogbo Olumo lohunlokan Olugbagbo Ododo gba gbo, won gba pe Olohun n be fun aye yi, sugbon awon miiran ti won saigbagbo won n be ninu iyemeji, ti won n lo, ti won n bo, ododo ni oro Olohun totobi ti o sope:

"أَمْ خُلِقُوا مِنْ غَيْرِ شَيْءٍ أَمْ هُمُ الْخَالِقُونَ {الطور/35} أَمْ خَلَقُوا السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ بَل لاَّ يُوقِنُونَ" {الطور/36}

“Abi won da won lasan laisi Aseda? Abi awon ni won da ara won ni? * Abi awon ni won da awon sanmo ati ile ni? Rara o, won ko ni imo amodaju ni” (Suurah a-t-Tuur: 35 – 36)

 Boya fifi opolo dajo nibi ti ko ti je dandan ki a ma fi opolo dajo lo sokunfa igunri kuro nibi esin, tori pe nibi oro eda Olohun bii re nikan lati maa n fi opolo dajo. Sugbon nipa Adeeda, kosi iro nibi pe opolo maa kagara nipa mimo on. Tori idi eyi ni Islaam se salaye oogun to n sise fun eyi. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) sope: "Esu to duro ti eni kookan yin yoo maa wa bayin ti yoo si maa so: Taani o da iyen, taani o da eyi, titi ti yoo fi so pe, taani o da Olohun re? Ti o ba ti ba de iru ibi yi, ki iru eni bee yara tete fi Olohun wa iso, ki o si jinna si I"

 

 

AWON ERI OPOLO LORI IJE OKAN SOSO OLOHUN

            Al – Qur’an Alapon le ti salaye gbigba danu oro wi pe orogun nbe fun Olohun, tabi Akegbe ati Afiwe, tori pe bibe Orogun fun Olohun je abuku, ati Aleebu ati gbogbo nnkan ti a Npe ni orogun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"هُوَ اللَّهُ الَّذِي لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ الْمَلِكُ الْقُدُّوسُ السَّلاَمُ الْمُؤْمِنُ الْمُهَيْمِنُ الْعَزِيزُ الْجَبَّارُ الْمُتَكَبِّرُ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يُشْرِكُونَ * هُوَ اللَّهُ الْخَالِقُ الْبَارِئُ الْمُصَوِّرُ لَهُ الأَسْمَاء الْحُسْنَى يُسَبِّحُ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ" {الحشر 23/24}

“Oun ni Olohuun, ko si Olohun ti ijosin to si afi Oun, Oba (eda), Eni mimo julo, Eni ti O la nibi gbogbo abuku, Eni ti gbogbo eda fokanbale si pe ko le se abosi, Olujeri lori gbogbo ise eda, Alagbara ti ko ni olubori, Olohun mo tayo ohun ti won n so di egbe fun Un * Oun ni Olohun, Eleda (Olupebubu eda), Olupile eda, Oluyaworan eda. TiRe ni awon oruko ti o dara ju lo. Gbogbo ohun to wa ninu awon sanmo ati ile n se afomo fun Un. Oun si ni Alagbara, Ologbon” (Suurah al – Hasr: 23 – 24)

Awon eri oro enu ati awon eri opolo, ti n be, ko fi le je pe yio gbe wa lo sibi lile mimu orogun mo Olohun lo ati gbigba orogun danu nibi eto o re, Ninu eri yi ni:

  • Bibe awon olohun miiran pelu Olohun, yio sodi dandan pe okookan awon olohun yi lo ni agbara to kari gbogbo nnkan niye – tori pe agbara lati le se gbogbo nnkan ninu awon iroyin Olohun lo wa, nipa bayi riro orogun fun Olohun, yio so di dandan pe ki enikan maa anife ohun to yapa sife enikeji, nipa bayi ariyanjiyan yio maa sele, biba ara eni ja, ati ikorira eni eleyi ti biba aye je maa sele latara re, tori idi eyi ni Olohun fi mo tayo koni orogun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لَوْ كَانَ فِيهِمَا آلِهَةٌ إِلاَّ اللَّهُ لَفَسَدَتَا فَسُبْحَانَ اللَّهِ رَبِّ الْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ" {الأنبياء/22}

 “Ti o ba je pe awon orisa ti ijosin to si tun wa ninu sanmo ati ile leyin Olohun ni, sanmo ati ile iba ti baje, Mimo ni fun Olohun Oluwa (to da) Ite – ola, kuro nibi gbogbo ohun ti won fi nroyin re” (Suurah al – Anbiyaa: 22)

  • Bibe awon olohun miiran pelu Olohun, yio so pipin aye simeji fun won di dandan, kofi le je pe okookan maa ko awon eda ti o da lo, beesi ni ibaje nla ti ko pamo fun onilaakaye Kankan ni n be ninu eyi. Eleyi kosi gbodo wa labala nnkan to ye fun Olohun. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"مَا اتَّخَذَ اللَّهُ مِن وَلَدٍ وَمَا كَانَ مَعَهُ مِنْ إِلَهٍ إِذًا لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَهٍ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلاَ بَعْضُهُمْ عَلَى بَعْضٍ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ" {المؤمنون/91}

“Olohun ko fi eni kankan se omo kosisi Olohun kan pelu Re (Ti ko bari bee) nigba naa Olohun kookan iba siti mu eda ti o da sodo, ti apakan won o si bori ara won, Olohun mo tayo iro ti un n pa (mo on)” (Suuratul Mumin: 91)

Bayi, Aso ni Olohun, Okansoso sini pelu, Nipa bayi Oba Aronukan ni, ko wa bukata si ko ni orogun Kankan ninu Ola re, ko si wa bukata si ko ni iyawo, koni omo be ni koni Oluranlowo Kankan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَقُلِ الْحَمْدُ لِلّهِ الَّذِي لَمْ يَتَّخِذْ وَلَدًا وَلَم يَكُن لَّهُ شَرِيكٌ فِي الْمُلْكِ وَلَمْ يَكُن لَّهُ وَلِيٌّ مِّنَ الذُّلَّ وَكَبِّرْهُ تَكْبِيرًا" {الإسراء/111}

“Ki o si so pe: gbogbo ope je ti Olohun, Eni ti ko fi eni kankan se omo, kosi ni egbera ninu Ijoba, koyepere ambosibosi pe O maa wa bukata si oluranlowo. Ki o si gbe titobi fun Un taara”. (Suurah al – Isroo: 111)

 Olohun ti Ola Re ga so pe:

"بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ أَنَّى يَكُونُ لَهُ وَلَدٌ وَلَمْ تَكُن لَّهُ صَاحِبَةٌ وَخَلَقَ كُلَّ شَيْءٍ وهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ" {الأنعام/101}

“Olupile eda awon sanmo ati ile ni. Bawo ni O se ni omo nigba ti ko ni aya. O da gbogbo nnkan. Oun si ni Onimimo nipa gbogbo nnkan” (Suurah al – Ani’aam: 101)

Nje Olohun ni bukata si awon eda Re?

Ninu nnkan ti a fi opolo mo ni pe eni ti o ba ni ikapa nkankan o ro lorun lati se ohun ti o ba wu u fun ohun ti o ni. tolohun ni apejuwe to ga julo.

Olohun ti o ga ti mimo je ti E ni Eledaa aye ati awon ohun ti o wa ninu re, Oun si loni ikapa re, OUn si ni o n dari re, ati ohun to wa ninu e bi o ba se fe, nigba to fe, nibikibi to ba fe, gbogbo eniyan patapata si je okan ninu eda Olohun , Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ رَبَّكُمُ اللّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَى عَلَى الْعَرْشِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ يَطْلُبُهُ حَثِيثًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ أَلاَ لَهُ الْخَلْقُ وَالأَمْرُ تَبَارَكَ اللّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ" {الأعراف/54}

OUN ni olupin ije – imu, Oludari – ise OUN lo n dari ojo, oda, owa riri ile iduro sinsin ile, osi, oro, isemi, iku, Alaafia, Aisan, Oriire, Ori buruku, gbogbo re n lo lori ogbon kan ti Olohun gbero, ati ase kan ti O pebubu, Nnkan kan ko lagbara ko salekun ebubu Olohun, tabi ki O gunri kuro nibi sise e re, (ohun ebubu) tabi ki o jade kuro nibi ijoba Re ati Erongba Re.

"لاَ يُسْأَلُ عَمَّا يَفْعَلُ وَهُمْ يُسْأَلُونَ" {الأنبياء/23}

“A ki i bi (Olohun) ni ibeere nipa nnkan ti O n se. Awon (eda) ni A oo bi ni ibeere (nipa ise owo won).” (Suurah al – ‘Arbiyya: 23)

Olohun tun so pe:

"وَرَبُّكَ يَخْلُقُ مَا يَشَاء وَيَخْتَارُ مَا كَانَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ سُبْحَانَ اللَّهِ وَتَعَالَى عَمَّا يُشْرِكُونَ" {القصص/68}

“Oluwa re ni O n seda ohun ti O ba fe. O si n sa (ohun ti O ba fe) ni esa. Sisa esa ko to si won. Mimo ni fun Olohun. O si ga tayo ohun ti won n fi se egbera (fun – Un). (Suurah al – Qosos: 68)

Nipa bayi, ogbon Olohun lori nnkan ni igba miran yio han, won o si damo, gege bi o tun se je pe yio pamo ni igba miran, eni Kankan o si ni moo, nigba miiran ohun ti o ba kadara, ti ode re buru, a maa je pe oore ni yio wa ninu re nigba miiran, ti awa kosi nii mo, a si maa je odikeji naa nigba miiran (Iyen ni pe ti ode maa dara, ti inu maa je aburu) Olohun ti Ola Re ga so:

"وَعَسَى أَن تَكْرَهُواْ شَيْئًا وَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ وَعَسَى أَن تُحِبُّواْ شَيْئًا وَهُوَ شَرٌّ لَّكُمْ وَاللّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لاَ تَعْلَمُونَ" {البقرة/216}

“O si le je pe e korira kini kan, ki ohun naa si je oore fun yin. O si tun le je pe e o nifee si kini kan, ki ohun naa si je aburu fun yin. Olohun nimo, eyin ko si nimo’ (Suurah al Baqoorah: 216)

Eni ti o lagbara lati mu eda be, gbodo lagbara ati le mu nnkan miiran naa be, iyen si n be ninu ohun ti Olohun mo ti awa ko mo, eleyi kosi ninu bukata adayanju fun ede Re, bi ko se pe won je eni ti yoo maa wa bukata si nnkan lodo Olohun, won si je talaka sodo Olohn nibi gbogbo oro won.

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يا أيها النَّاسُ أَنتُمُ الْفُقَرَاء إِلَى اللَّهِ وَاللَّهُ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ * إِن يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ * وَمَا ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ بِعَزِيزٍ {فاطر15/17}

“Eyin eniyan, eyin ni alaini (tie ni bukata) si Olohun. Olohun, Oun ni Oloro, Oloore* Ti O ba fe, O maa ko yin kuro nile. O si maa mu eda titun wa * Iyen ko si le kagara kan ba Olohun” (Suurah Faatir: 15 – 17)

Gege bi o se je pe awon ara awon eda Olohun maa n wa awon nnkan ti yio gbe isemi won ro, bii ohun jije, ohun mimu, naa ni awon emi won wa bukata si Eledaa ti won yoo maa sin, ti yoo maa bawon so bibiya bukata kale, ti won yoo si maa yepere ara a won niwaju e, ti won yoo maa ri ifokanbale nibi sisunmo on. Gege bi omode se maa n da ifokanbale mo to ba wa lowo baba re gele ni eda abara se maa n ri nibi bukata ti Adede yoo maa ba biya, won yoo ma yepere niwaju Re, won yoo si maa kibosi ohun ti won n fe wa sodo re, laarin iyepere ara eni, sisin Adedaa ni emi ti maa n jeun, ti o ti maa n ri ifokanbale, tosi ti maa n soriire, kosi le lagbara a ti le de ibi onje yii ayafi ki o gba ona odo awon Ojise Olohun awon ti won n mu ise imisi mimo wa latodo Adedaa ti o da emi re, ti o si se onje re ni nnkan ti yio maa be nibi ohun ti awon Ojise Olohun ba mu wa ninu ofin esin Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَلاَ يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ" {الملك/14}

“Se Olohun ko mo eni ti O da ni? Oun si ni Olohun, Alamotan” (Suurah Al – Mulk: 14)

E o ri bibe, mimaa semi awon eda abara, ati lilo bibo won nibi gbogbo ise won, lon seri si ife ati erongba Olohun. Ko da lilo bibo mo won kofi le lagbara, won o si dawon fun ere -mode tabi ere – agbalagba, won o si dawon fun a ti le se anfaani kan fun Olohun tabi ko inira kan ba A. olohun roro tayo won, Awon si je alaini sodo Olohun, gege bi Olohun se royin eyi ninu Hadith mimo bayii:

"Eyin erusin mi, e o lagbara lati fara ni mi, ti e o fi wa fara ni Mi, e o si le semi lanfaani Kankan, ti e o fi wa se Mi lanfaani naa, eyin erusin Mi, ti o ba je pe, eni akoko yin, eni ikeyin yin, eniyan inu yin, Alijannu inu yin , ti won ba n be gege bi okan eni ti o paya Olohun ju ninu yin, iye ko le nkakan kun ninu ola Mi, eyin erusin Mi, ti o ba je pe, eni akoko yin, eni ikeyin yin, eniyan inu yin, Alijannu inu yin, ti won ban be gege bi okan eni ti o ya poki ju ninu yin, iye ko din nkankan ku ninu ola Mi, eyin erusin Mi, ti o ba je pe, eni akoko yin, eni ikeyin yin, eniyan inu yin, Alijannu inu yin, ti won ba duro si aye kan, ti won si bere nkan lowo Mi, ti Mosi fun gbogbo, iye ko din nkankan ku ninu ohun ti n be lodo Mi, ayafi bi abere se maa ndi omi ku nigba ti won ba ki bo inu ibudo, dajudaju awon ise yin Moti se onka re fun yin, eni ti o ba ri daada ki o dupe fun Olohun, eni ti o ba ri idakeji iye ki o ma bu enikankan ayafi ara re". (muslim)

Gbogbo ise ominiyan patapata ni yio seri pada si won. Ko ba je anfaani tabi inira bakan naa ni won yoo se ri nibi isiro, ti o ba je ise – rere, omoniyan yoo ri esan rere, to ba je ise buruku, omoniyan yoo ri esan buruku, ninu ike Olohun ati deede Olohun lo fa esan, isiro, esan rere ati ibawi, kofi le je pe egbin ati ohun mimo konii dogba papa. Olohun ti Ola re ga so pe:

"إِنْ أَحْسَنتُمْ لإِنفُسِكُمْ وَإِنْ أَسَأْتُمْ فَلَهَا فَإِذَا جَاء وَعْدُ الآخِرَةِ لِيَسُوؤُواْ وُجُوهَكُمْ وَلِيَدْخُلُواْ الْمَسْجِدَ كَمَا دَخَلُوهُ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَلِيُتَبِّرُواْ مَا عَلَوْاْ تَتْبِيرًا" {الإسراء/7}

“Ti e ba se rere, e se rere fun emi ara yin. Ti e ba se aburu, fun emi are yin ni. nigba ti adehun ikeyin ba de, (A oo gbe omo ogun miiran dide) nitori ki won le ko ibanuje ba yin ati nitori ki won le wo inu Mosalasi gege bi won se wo o nigba kin-in-ni ati nitori ki won le ko iparun nlanla ba ohunkohun ti (awon omo ‘Isroo’ill) joba le lori” (Suurah al – Isroo: 7)

 

 

AWON OHUN TOSOKUNFA DIDA EDA ABARA

Kororun fun onilaakaye kan ayafi ko maa gba pe won o le sadede da awon nnkan ayafi ko je pe o ni awon ogbon ti won fee fayo nibe. Eniyan toni laakaye ko ni maa ti ara re lo sibi sise awon nnkankan ninu isemi aye re laini ogbon kan ati erongba kan to fe fayo nibe, bawo le se waa lero pe oro yio ri fun Olohun Oba Ojogbon ti o gbon ju Gbogbo on ti o logbon miiran lo? Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لِكُلٍّ جَعَلْنَا مِنكُمْ شِرْعَةً وَمِنْهَاجًا وَلَوْ شَاء اللّهُ لَجَعَلَكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَلَكِن لِّيَبْلُوَكُمْ فِي مَآ آتَاكُم فَاسْتَبِقُوا الخَيْرَاتِ إِلَى الله مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ" {المائدة/48}

“Olukuluku ninu yin lati se ofin ati ilana fun ati pe ti o ba je pe Olohun ba fe ko ba se yin ni ijo kan soso (sinu) Islaam, sugbon nitori ki o le danyiwo ninu ohun ti o fun yin ni, Nitori naa e gba iwaju nibi ise rere. Odo Olohun ni abo gbogbo yin patapata. Nigba naa, Olohun yoo fun yin ni iro nipa ohun ti e n yapa enu si.” Suurah al – mooidha: 48)

Dajudaju gbogbo eda tolohun da sile aye yii, o da a fun idi kan tokun fogbon ni, idi yi ko si je bibe ayafi ki o je pe titori atunse re, yala a mo on tabi a ko mo on. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاء وَالأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا بَاطِلاً ذَلِكَ ظَنُّ الَّذِينَ كَفَرُوا فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا مِنَ النَّارِ" {ص/27}

“A ko da awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin won fun (iranu), iye ni ero awon ti won saigbagbo. Nitori naa, egbe ni fun awon ti won saigbagbo ninu ina”

(Suurrah Sood: 27)

Ni ti afihan mimo, ko dandan ki o je pe ibeere wa ni pe, tori kinni Olohun fi da eda abara, sugbon o leto ki ibeere je pe ohun ti a maa beere ni, kinni idi to kun fun ogbon to wa lara dida tolohun fi da eda abara. Ati pe kinni nkan ti o n fe lowo won nipa dida won?

Ogbon ti n be nibi dida eda, enikan kole mo on ayafi Olohun to gbon – ngbon, ti Ola Re ga, ako le mo ogbon to wa nibe ayafi eyi ti O salaye fun wa nikan (mimo ati giga fun Olohun) Olohun ti salaye pe ogbon OUN Olohun nibi dida sanmo ati ile, ati ohun to wa ninu mejeeji ninu awon eda, OUN Olohun to se pe kosi eni tole mo Oun ayafi OUN naa, a ti se idanwo fun eda abara. Gege bi Olohun Oba mimo ti Ola Re ga se so bayi pe:

"وَهُوَ الَّذِي خَلَق السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ وَكَانَ عَرْشُهُ عَلَى الْمَاء لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلاً" (سورة هود:7)

“(Olohun) Oun ni Eni ti O da awon sanmo ati ile fun ojo mefa – Ite ola Re si ti wa lori omi (Siwaju eyi) – nitori ki O le dan yin wo” (Suurah Huud: 7)  

            Olohun ko da isemi ati iku ayafi ko je pe idi pataki yi lo fa a. nipa bayi, awon asiko isemi aye ti a o lo ti wa ni ipebubu (ohun ti a bugbasi) Ise ti a o si se nibe ti wa ni dide pa, O si ti wa lakosile, bakan naa igba to wa laarin iku ati iye si ni aye idanwo naa. Iyen si ri bee ko fi le fojuhan laarin re, Eniire ati Eniibu, Olugbagbo Ododo ati Alaigbagbo. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِي خَلَقَ الْمَوْتَ وَالْحَيَاةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلاً وَهُوَ الْعَزِيزُ الْغَفُورُ" {الملك/2}

“eni ti o da iku ati isemi, ki O le gbidanwo yin, tani ise re yio dara julo ninu yin, Oun ni Oba-nla, Alaforijin"(Suurah al-Mulk: 2)

Idanwo je kadara Olohun (oba ti o mo ti Ola Re ga) lori baba eda abara ti i se Adam (ki Ola Olohun maa ba a) lasiko igba towa Lalujannah, nigba ti Olohun pa oun ati iyawo re lase pe won ko gbodo je eso igi to ni ki won ma je, Esu ko royiroyi ba won, (Adam) si tele ase esu, o si yapa ase Olohun re o si pada jewo ese re, o ronupiwada, Olohun si gba ironupiwada re, o si so ka ori ile aye, ki aye fi le je aye idanwo ati adanwo fun un, ati fun awon omo re leyin re. olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَقُلْنَا يَا آدَمُ اسْكُنْ أَنتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ وَكُلاَ مِنْهَا رَغَداً حَيْثُ شِئْتُمَا وَلاَ تَقْرَبَا هَذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الْظَّالِمِينَ * فَأَزَلَّهُمَا الشَّيْطَانُ عَنْهَا فَأَخْرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِ وَقُلْنَا اهْبِطُواْ بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ وَلَكُمْ فِي الأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَى حِينٍ * فَتَلَقَّى آدَمُ مِن رَّبِّهِ كَلِمَاتٍ فَتَابَ عَلَيْهِ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ * قُلْنَا اهْبِطُواْ مِنْهَا جَمِيعاً فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدًى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ * وَالَّذِينَ كَفَرواْ وَكَذَّبُواْ بِآيَاتِنَا أُولَئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ" {البقرة: 35/39}

“A tun so pe “Iwo Aadam, iwo ati iyawo re, e maa gbe ninu Ogba Idera. Ki e maa je nibe ni gbedemuke ni ibikibi ti e ba fe. Ki e si maa se sunmo igi yii, ki e maa ba wa ninu awon alabosi * Amo Esu ye awon mejeeji lese kuro ninu Ogba Idera o si mu won jade kuro ninu ibi ti won wa. A si so pe: “E sokale ota ni apa kan yin je si apa kan. Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin ni or ile fun igba (die) * leyin naa, (Anabi) Aadam ri awon oro kan gba lati odo Oluwa re Olohun si gba ironupiwada re. dajudaju Oun ni Olugba ironupiwada Alaaanu * A so pe: “Gbogbo yin, e sokale kuro ninu re. nigba ti itosona ba de bayin lati odo Mi, nigba naa eni ti o ba tele itosona Mi, iberu ko ni si fun won. Won ko si ni banuje * Awon ti won ba saigbagbo, ti won si pe awon aayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina Olusegbere ni won ninu re”. (Suurah al – Baqorah: 36 – 39)

Nitori Ogbon ti Olohun gba lero lo fi se awon eda abara ni arole lori ile leyiin baba nla won Adam (ki ike Olohun maa ba a) Abala awon eniyan kan wa n role fun omiran kofi le je pe adanwo ti Olohun ti pebubu re maa duro daadaa. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَهُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلاَئِفَ الأَرْضِ وَرَفَعَ بَعْضَكُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ لِّيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ إِنَّ رَبَّكَ سَرِيعُ الْعِقَابِ وَإِنَّهُ لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ" {الأنعام/165}

“(Olohun) Oun ni Eni ti o se yini ni arole lori ile, O si gbe awon apakan yin ga ju apakan lo nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin. Dajudaju Oluwa re ni Oluyara nibi iya. Dajudaju Oun si ni Alaforiji, Alaaaanu” (Suurah al – Ani’aam: 165)

Tori idi eyi, lo fi je pe iyapa enu laarin awon eda abara je isesi ti Olohun fi lele laye yii. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَوْ شَاء رَبُّكَ لَجَعَلَ النَّاسَ أُمَّةً وَاحِدَةً وَلاَ يَزَالُونَ مُخْتَلِفِينَ" {هود/118}

“Ti o ba je pe Oluwa re fe bee ni, iba se gbogbo eniyan ni ijo elesin kan soso (Amo) won ko nii ye maa yapa enu (si Islaam)” (Suurah Huud: 118)

Kofi le je pe yio maa be ninu awon eniyan olugbagbo ododo, Alaigbagbo Eniire, Eniibi, ati kofi le je pe igbedale o maa wa laarin daadaa ati aburu, titi di ojo igbende, ko fi le je pe ododo maa han yato si iro, ti deede Olohun fi maa han laarin awon eniyan, ti yoo fi wa san eni ti o tele ase Re ni esan rere, ti yoo si fi fiya je eni ti o yapa ase Re, Olohun ti Ola re ga so pe:

"فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُواْ وَعَمِلُواْ الصَّالِحَاتِ فَيُوَفِّيهِمْ أُجُورَهُمْ وَيَزيدُهُم مِّن فَضْلِهِ وَأَمَّا الَّذِينَ اسْتَنكَفُواْ وَاسْتَكْبَرُواْ فَيُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا أَلُيمًا وَلاَ يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ اللّهِ وَلِيًّا وَلاَ نَصِيرًا" {النساء/173}

 

“Ni ti awon ti won ba gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, (Olohun) yoo san won ni esan won ni ekun rere. O si maa se alaekun fun won ninu oore ajulo Re. Awon ti won ba si ko (lati josin fun Olohun), ti won tun segberaga, (Olohun) yoo je won niya eleta – elero. Won ko nii ni alatileyin tabi alaranse kan kan leyin Olohun” (Suurah a-n-Nisaa: 173)

 Idanwo lori titele ase – Olohun ati iyapa ase – Olohun ni idi kan ninu awon idi to wa fun dida eda abara, kofi le je pe Olododo a fara han laarin opuro, Olugbagbo ododo naa o fara han laarin alaigbagbo, eleyi tosi je pe Olohun ti mo teletele ko to dipe O sele, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا كَانَ اللّهُ لِيُطْلِعَكُمْ عَلَى الْغَيْبِ وَلَكِنَّ اللّهَ يَجْتَبِي مِن رُّسُلِهِ مَن يَشَاء فَآمِنُواْ بِاللّهِ وَرُسُلِهِ وَإِن تُؤْمِنُواْ وَتَتَّقُواْ فَلَكُمْ أَجْرٌ عَظِيمٌ" {آل عمران/179}

“Olohun ko si nii fi imo ikoko han yin, sugbon Olohun yoo sesa eni ti O ba fe ninu awon Ojise Re. Nitori naa, e ni igbagbo ododo ninu Olohun ati awon Ojise Re. Ti e ba gbagbo ni ododo ti e si beru (Olohun) esan nla yoo si wa fun yin” (Suurah aali-Imroon: 179)

 Ninu idanwo to tobi ti Olohun ti tori re da eda abara ni mimu Olohun lokan, ati mi maa sin Olohun nikan soso, ti kosi sorogun fun un, gege bi Olohun ti Ola Re ga se soro yi bayi pe:

"وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالإِنسَ إِلاَّ لِيَعْبُدُونِ * مَا أُرِيدُ مِنْهُم مِّن رِّزْقٍ وَمَا أُرِيدُ أَن يُطْعِمُونِ * إِنَّ اللَّهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ {الذاريات 86/58}

“Ati pe Emi ko se eda alujannu ati eniyan lasan bi ko se pe ki won le maa josin fun Mi. * Emi ko gbero arisiki kan kan lati odo won. Emi ko si gbereo pe ki won maa bo Mi. * Dajudaju Olohun Oun ni Olupese Alagbara to le koko” (Suurah a – th – Thaariyaat: 56 – 58)

 Kosi ninu agboye eleyi pe Olohun da eda fun ki won o maa josin nitori bukata Olohun to fee gbo, bi ko se pe Olohun je Oluroro kuro lodo won, O roro kuro nibi awon ise won, awon eda gan –an ni yoo ma gbe bukata wa ba Olohun, won o roro kuro nibi wiwa Olohun, titele ase – Olohun awon eniyan ko se Olohun lanfaani Kankan, bakan naa yiyapa ase Olohun won ko konira Kankan ba A. Toripe oba to roro funra ra re ni kuro lodo eyikeyi nnkan miiran to yato Sii. Sugbon oranyan ni fun awon eru Re ki won o maa sin In, ki won si maa tele ase Re. olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا النَّاسُ أَنتُمُ الْفُقَرَاء إِلَى اللَّهِ وَاللَّهُ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ" {فاطر/15}

“Eyin eniyan, eyi ni alaini (ti e ni bukata) si Olohun. Oun ni Oloro Eleyin” (Suurah Fajir: 15)

O si tun je dandan ki won o maa yin IN, ki won si maa dupe fun UN. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِن تَكْفُرُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ عَنكُمْ وَلاَ يَرْضَى لِعِبَادِهِ الْكُفْرَ وَإِن تَشْكُرُوا يَرْضَهُ لَكُمْ وَلاَ تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَى ثُمَّ إِلَى رَبِّكُم مَّرْجِعُكُمْ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ" {الزمر/7}

“Ti eyin ba se aimore dajudaju Olohun roro tayoyin, (ko si ni bukata si yin). Ko si yonu si aimooore fun awon erusin re. Ti eyin ba dupe, O maa yonu si i fun yin, Eleru – ese kan ko si nii ru eru ese elomiran. Leyin naa odo Oluwa yin ni abo yin. O si ma fun yin ni iro ohun ti e n se nise. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba – aya” (Suurah a-z-Zumoor: 7)

 Latari eyi lo fi ye wa pe Olohun ti Ola Re ga. Ko da eda abara nitori kan fi le maa jeun, maa mu, ati kan fi le maa wa opo dukia lasan, ti yio fi wa dipe awon naa o waa da bi awon eran osin. Olohun ti Ola re ga ti ponwonle pelu laakaye, o si ti dawon lola ju opolopo awon eda ti O da lo, ni Ola kan ti o po pupo. Sugbon opolopo eniyan ko lati sin Olohun, bi ko se pe won saigbagbo won saimokan tabi ka pe won jiyan tako ojulo ogbon to pamo sibi dida won. Lo fi di wi pe gbogbo ero okan won ni pe ki won sa ti gbadun pelu gbogbo ojukokoro adun aye, ki won je ajeyo fun abe won, inu won, gege bi Olohun ti so nipa won, isemi aye awon wonyi da gege bi isemi awon eran – osin, tabi ki a so pe, won tun sonu ju eran – osin lo, iyen ri bee fun ai lo opolo ti O fun won, ti O si fi sa won lesa laarin awon eda Re, ki won fi le ronu nipa dida won, ati nipa ohun tosokunfa bibe won. Olohun ti Ola re ga so:

"وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ" {محمد/12}

“Awon ti won si saigbagbo n gbadun, won si n je (kiri) gege bi awon eran – osin se n je (kiri). Ina si ni ibugbe fun won” (Suurah Muhammad: 12)

 Won kosi tun gboye pe, idanwo ti Olohun fi aye se yii je ohun ti o duro lori aburu, ohun ti ko mu inu eniyan dun, ohun to maa n sele laye yii ninu awon idekun naa wa lara idanwo naa whala idaamu naa wa lara idanwo bakan naa Olohun ti Ola Re ga so bayii nipa itan Annabi Olohun ti n je Sulaiman, eni ti Olohun da lola pelu jije Oba, ti Olohun si fun ni oore ti ko fun elomiran ni iru re laye, nigbati o so fun awon to n daje ki won lo ba oun gbe aga ola Balqiis wa, Olohun so pe:

"قَالَ الَّذِي عِندَهُ عِلْمٌ مِّنَ الْكِتَابِ أَنَا آتِيكَ بِهِ قَبْلَ أَن يَرْتَدَّ إِلَيْكَ طَرْفُكَ فَلَمَّا رَآهُ مُسْتَقِرًّا عِندَهُ قَالَ هَذَا مِن فَضْلِ رَبِّي لِيَبْلُوَنِي أَأَشْكُرُ أَمْ أَكْفُرُ وَمَن شَكَرَ فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ رَبِّي غَنِيٌّ كَرِيمٌ" {النمل/40}

“Eni ti imo nkan lati inu tira wa ni odo re so pe: “Emi yoo gbe e wa fun o siwaju ki o to seju. Nigba ti o ri ti o de si odo re, o so pe: “Eyi wa ninu oore ajule Oluwa mi, lati fi dan mi wo boya emi yoo dupe tabi emi yoo saimoore. Enikeni ti o ba dupe (fun Olohun), o ma dupe fun ori ara re ni. enikeni ti o ba si saimoore, dajudaju Oluwa mi ni Oloro Alaponle” (Suurah a-n-Naml: 40)

 Bakan naa ni gbogbo nnkan to n sele ninu iya jije, ati awon inira ati awon nnkan miiran ni ile aye yii naa wa lara idanwo. idaamu ti o maa n sele somoniyan naa wa lara idanwo. olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَنَبْلُوَنَّكُمْ بِشَيْءٍ مِّنَ الْخَوفِ وَالْجُوعِ وَنَقْصٍ مِّنَ الأَمَوَالِ وَالأنفُسِ وَالثَّمَرَاتِ وَبَشِّرِ الصَّابِرِينَ * الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُم مُّصِيبَةٌ قَالُواْ إِنَّا لِلّهِ وَإِنَّا إِلَيْهِ رَاجِعونَ * أُولَئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِّن رَّبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ وَأُولَئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ {البقرة 155/157}"

“Dajudaju A o maa dan yin wo pelu kini kan latara ipaya ati ebi ati adinku ninu awon dukia, awon emi ati awon eso. Ki o si fun awon onisuuru ni iro idunnu * Awon ti (o je pe) nigba ti adanwo kan ba kan won, Won o so pe: “Dajudaju Olohun lo ni wa, Dajudaju odo Re si ni a maa pada si* Awon wonye ni aforijin ati ike yoo ma be fun lati odo Oluwa won. Awon won ye si ni olumona”.” (Suurath al – Baqoah: 155 -157)

 

 

 

AWON ERI OPOLO LORI IGBENDE LEYIN IKU LATI INU AL – QUR’AAN

Omoniyan maa n se iyanu nipa rirorun igbende re leyin iku, ati dida emi re pada nigba keji, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَيَقُولُ الإِنسَانُ أَئِذَا مَا مِتُّ لَسَوْفَ أُخْرَجُ حَيًّا * أَوَلاَ يَذْكُرُ الإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن قَبْلُ وَلَمْ يَكُ شَيْئًا{مريم66/67}

“Eniyan n wipe: “Se nigba ti mo ba ku, won yoo tun mu mi jade laipe ni alaaye bi?” * Se eniyan ko ranti pe dajudaju Awa ni a se eda re teletele nigba ti ko ti je nnkan kan?” (Suurah Moryam: 66 – 67)

 Nipa bayi Olohun salaye pe ohun ti awon ti won n satako igbende leyin iku gbagbo nipe ohun ti kole rorun ni sise re. Olohun so pe ohun to rorun pupo ni fun eni ti o se pe ti o ba ti ni ki nnkankan maa ri bee, yio si maa ri bee. Olohun ti Ola Re ga so bayii, nipa won pe:

"زَعَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَن لَّن يُبْعَثُوا قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ وَذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ" {التغابن/7}

“Awon to saigbagbo lero pe A o nii gbe won dide. So pe: “Bee ko, mo fi Oluwa mi bura, dajudaju Won yoo gbe yin dide. Leyin naa, Won nyoo fun yin ni iro ohun ti e se nise. Iyen si je irorun fun Olohun” (Suurah a- Tagooobun: 7)

 Ninu iwoye si awon alatako igbende, a ri pe won o gbarale nnkankan lori eyi bi ko se pe awon eri opolo ti won mo, Al – Qur’aan si salaye ohun ti o baa mu fun won nipa mimu eri wa pe ohun ti o rorun ni eleyi o, o si salaye lona ti o ba mu fun won wi pe won safeku igbagbo nipa igbende leyin iku ati nipa akojo ojo igbende, ninu bi alaye naa se lo niyii:

  • Eni ti o kappa lati mu eda be latara aisi o ye kole rorun fun un lati gbe eda dide pada leyin iku, nitori pe dida nnkan kan ti n be tele to pada tan je ohun ti o rorun ju ibere nkan lo. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ وَلَهُ الْمَثَلُ الأَعْلَى فِي السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ" {الروم/27}

 “Oun ni eni ti O n bere eda dida. Leyin naa O maa da a pada (sipo alaaye fun ajinde), o si rorun ju lo fun Un, (lati se bee). Ti Re ni apejuwe ti o ga ju lo ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon” (Suurah a – Ruum: 27)

Ubayy omo Khalaf waa ba Anabi (ki Ike ati Ola maa ba a) leni ti o mu eegun kan to ti kefun lowo o so pe: Iwo Muhammad, se o lero pe Olohun tun le so eyi di alaaye leyin ti o ti kefun bi? Ojise Olohun (ki ike ati Ola maa ba a) dahun pe: Beeni, yoo tun gbe o dide leyin iku, yoo si fi o sinu ina.

Nitori idi eyi, Olohun ti Ola Re ga so oro Re yii kale:

"وَضَرَبَ لَنَا مَثَلاً وَنَسِيَ خَلْقَهُ قَالَ مَنْ يُحْيِي الْعِظَامَ وَهِيَ رَمِيمٌ * قُلْ يُحْيِيهَا الَّذِي أَنشَأَهَا أَوَّلَ مَرَّةٍ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ * الَّذِي جَعَلَ لَكُم مِّنَ الشَّجَرِ الأَخْضَرِ نَارًا فَإِذَا أَنتُم مِّنْهُ تُوقِدُونَ * أَوَلَيْسَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ بِقَادِرٍ عَلَى أَنْ يَخْلُقَ مِثْلَهُم بَلَى وَهُوَ الْخَلاَّقُ الْعَلِيمُ * إِنَّمَا أَمْرُهُ إِذَا أَرَادَ شَيْئًا أَنْ يَقُولَ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ * فَسُبْحَانَ الَّذِي بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ {يس78/83}

“O si fi apejuwe lele fun Wa. O si gbagbe iseda re, O wi pe: “Ta ni O maa so egungun di alaaye nigba ti o ti kefun?” * So pe: Eniti O maa so o di alaaye ni eni ti O se eda re ni igba akoko. Oun si ni Olumo nipa gbogbo eda. * (Oun ni) Eni ti O mu ina jade fun yin lati are igi tutu. (Sebi leyin) igba naa ni e n fi ko ina. * Nje Eni ti O da awon sanmo ati ile ko ni agbara lati da iru won ni? Rara (O ni agbara) Oun si ni Eledaa, Olumo. * Ohun ti o je ase Re nigba ti O ba gbero kini kan ni ki O maa so fun un pe “Je bee” O si maa je be. * Nitori naa, mimo ni fun Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo re. odo Re si ni won yoo da yin pada si” (Suurah Yaasiin: 78 – 83)

Tafsir Abdul Rozaaq (2498 87/3) ati Baeyyaqi ati itaa kinni o je ohun to ni alaafia (Siiroh, Ojuewe 201)

 Idi niyen ti Olohun ti o mo julo ti Ola Re si ga fi pase fun Ojise Re ti i se Muhammad (ki ike ati Ola maa ba a) pe ko so bayii fun awon alaigbagbo ti won bi leere (nipa igbende leyin iku)

"وَقَالُواْ أَئِذَا كُنَّا عِظَامًا وَرُفَاتًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ خَلْقًا جَدِيدًا" {الإسراء/49}

“Won si wi pe: “Se nigba ti a ba ti di egungun ati erupe, se nibga naa ni awa maa di eni ti won yoo gbe dide ni eda tuntun?” (Suurah al – Isroo: 49)

Olohun ni ko dawon lohun ni ibamu si agbekale oro won

"قُل كُونُواْ حِجَارَةً أَوْ حَدِيدًا * أَوْ خَلْقًا مِّمَّا يَكْبُرُ فِي صُدُورِكُمْ فَسَيَقُولُونَ مَن يُعِيدُنَا قُلِ الَّذِي فَطَرَكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ فَسَيُنْغِضُونَ إِلَيْكَ رُؤُوسَهُمْ وَيَقُولُونَ مَتَى هُوَ قُلْ عَسَى أَن يَكُونَ قَرِيبًا * يَوْمَ يَدْعُوكُمْ فَتَسْتَجِيبُونَ بِحَمْدِهِ وَتَظُنُّونَ إِن لَّبِثْتُمْ إِلاَّ قَلِيلاً" {الإسراء 50/52}

“So pe: E di okuta tabi irin. * Tabi (ki e di) eda kan ninu ohun ti o tobi ninu okan yin”. Sibesibe won yoo wi pe: “Ta ni O maa da wa pada (fun ajinde)?” so pe: “Eni ti O pile iseda yin ni igba akoko ni”, Sibesibe won yoo mi ori won si o (ni ti abuku) . nigba naa won yoo wi pe: “Igba wo ni? “so pe: O le je pe o ti sunmo” * Ojo ti (Olohu) yoo pe yin. Eyin yoo si jepe pelu idupe fun Un. Eyin yo si ro pe e o gbe ile aye ju igba die lo” (Suurah al – Isroo: 50 - 52)

 Sise nnkan ni igba keji maa n rorun ju sise e ni igba akoko lo ninu laakaye. Eni ti o da o nigba akoko ni agbara lati da o nigba keji naa. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَيَحْسَبُ الإِنسَانُ أَن يُتْرَكَ سُدًى * أَلَمْ يَكُ نُطْفَةً مِّن مَّنِيٍّ يُمْنَى * ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّى * فَجَعَلَ مِنْهُ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالآنثَى * أَلَيْسَ ذَلِكَ بِقَادِرٍ عَلَى أَن يُحْيِيَ الْمَوْتَى {القيامة 36/40}

“Se eniyan lero pe A maa fi oun sile lasan ni? * Se ko ti je ato ti nda jade sinu apoluke ni? * leyin naa, o di eje didi (Olohun) si se eda (re). o si se ni dogba jale leeynan. * (Olohun) si se iran meji jade lati inu re, ako ati abo. * Nje Eni ti O se iye ko ni agbara lati ji awon oku dide bi?” (Suurah al- Qiyaamoh: 36 – 40)

  • Eniti o da ohun ti o soro ju, maa ni agbara a ti le da eyi ti o rorun julo, gbogbo re patapata lo si rorun lodo Olohun fun apeere, eni ti o ba lagbara ati le gbe `aadota kilo, koni ko agara ati gbe kilo eyokan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَوَلَيْسَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ بِقَادِرٍ عَلَى أَنْ يَخْلُقَ مِثْلَهُم بَلَى وَهُوَ الْخَلاَّقُ الْعَلِيمُ* إِنَّمَا أَمْرُهُ إِذَا أَرَادَ شَيْئًا أَنْ يَقُولَ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ * فَسُبْحَانَ الَّذِي بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ {يس81/83}

"nje Eni ti O da awon sanmo ati ile koni ni agbara lati da iru won, beeni! Oun ni Adeda, Olumo, * Ohun ti o je ase Re nigba ti O ba gbero kini kan ni ki O maa so fun un pe “Je bee” O si maa je be. * Nitori naa, mimo ni fun Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo re. odo Re si ni won yoo da yin pada si” (Suurah Yaasiin: 81 – 83)

  • Eni ti o da o laisi ero – okan fun o imo re ni ibere ninu ohun to ba opolo mu ni pe o maa ni agbara a ti le da o nigba keji naa laisi ero re ati imo re nibe. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَيَقُولُ الإِنسَانُ أَئِذَا مَا مِتُّ لَسَوْفَ أُخْرَجُ حَيًّا * أَوَلاَ يَذْكُرُ الإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن قَبْلُ وَلَمْ يَكُ شَيْئًا * فَوَرَبِّكَ لَنَحْشُرَنَّهُمْ وَالشَّيَاطِينَ ثُمَّ لَنُحْضِرَنَّهُمْ حَوْلَ جَهَنَّمَ جِثِيًّا * ثُمَّ لَنَنزِعَنَّ مِن كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمْ أَشَدُّ عَلَى الرَّحْمَنِ عِتِيًّا {مريم66/69}

“Eniyan n sope: “Se nigba ti mo ba ku, won yoo tun mu mi jade laipe ni alaaye bi?” * Se eniyan ko ranti pe dajudaju Awa ni a se eda re teletele nigba ti ko ti je nnkan kan? * Nitori naa mo fi Oluwa re bura, dajudaju A maa ko won ati awon esu jo, Leyin naa, Dajudaju A maa mu won wa si ayika ina Jaanamo lori ikunle * Lehin naa, dajudaju A maa mu jade ninu ijo kookan eyikeyi ninu won ti o le ju lo ni ese dida si Ajoke aye.” (Suurah Moryam: 66 – 69)

 Ni odo Olohun, bakan naa ni dida eyo eda kan ati dida opo eda ri, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"مَّا خَلْقُكُمْ وَلاَ بَعْثُكُمْ إِلاَّ كَنَفْسٍ وَاحِدَةٍ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ" {لقمان/28}

“Iseda yin ati ajinde yin kotayo bi (iseda ati ajinde) emi kan soso, Dajudaju Olohun ni Olugbo, Oluri” (Suurah Luqmoon: 28)

 Eni ti o yi ipele dida eda lati isesi kan si omiran, ati eronja dida eda lati isesi kan si omirnan, ti O n mu alaaye jade lati inu oku, tabi ka pe to n mu oku jade lati ara alaaye, O gbodo ni agbara lori ati gbe oku dide nigba to se pe Olohun n mu horo irugbin to je alaaye jade latara horo irugbin to ti doku. O si n mu horo rugbin to je oku jade latara irugbin aaye, o mu igi to je aaye jade latara eso dabidun to ti ku, o si n mu eso dabidun to ti ku jade latara igi aaye. OUN si ni o n mu oku eyin jade latara abo – adie aaye, o si n mu oromodie aaye jade lati ara oku eyin. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ اللّهَ فَالِقُ الْحَبِّ وَالنَّوَى يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَمُخْرِجُ الْمَيِّتِ مِنَ الْحَيِّ ذَلِكُمُ اللّهُ فَأَنَّى تُؤْفَكُونَ * فَالِقُ الإِصْبَاحِ وَجَعَلَ اللَّيْلَ سَكَنًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ حُسْبَانًا ذَلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ" {الأنعام 95/96}

“Dajudaju Olohun ni n mu koro eso irugbin ati koro eso dabidun hu jade, O n mu alaaye jade lati ara oku, O si n mu oku jade lati ara alaaye (Eni ti n se awon nnkan) wonyi ni Olohun, Nitro naa, bawo ni e se nda adapa iro? * Olu mu ojumo jade, O se oru ni isinmi. (O si se) oorun ati osupa ni nnkan isiro fun ojo aye. Iye ni eto Alagbara, Olumo” (Suurah al – Ani’aam)

Eni ti o mu awon irugbin ati awon igi jade lati inu oku ile leyin ti ojo ti ro si I, to si ti je ile okoo tele, O ni agbara lori igbende leyin iku ati ikojo Ojo ikeyin. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَاللَّهُ الَّذِي أَرْسَلَ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَسُقْنَاهُ إِلَى بَلَدٍ مَّيِّتٍ فَأَحْيَيْنَا بِهِ الأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا كَذَلِكَ النُّشُورُ "{فاطر/9}

“Olohun ni Eni ti o fi awon ategun ranse, (Ategun naa) si maa tu esujo jo wa soke, A si fi fun ilu kan (ti ile re) ti sa ni omi mu, Leyin naa, A fi ta ile ji leyin ti o ti sa, Baye ni ajinde (eda yo se ri)”.” (Suurah Faatir: 9)

  • Eni ti o da omoniyan lati ibi aisi ni ipele ipele ti yoo la koja titi ti yoo fi ku, ni agbara lori gbigbe dide nigba keji, iku si ko ni ipele ikeyin fun ominiyan, bi ko se pe igbende ti won yoo se isiro ise lori ohun ti o ti siwaju fun un nibe, maa tele iku ni, nipa bayi, ko leto ki eniyan tako igbende, besi ni kosi idi kan to fa eyi ju pe won o ri i lo, Eni ti o da a ni ipile, ti o fi n sipo kuro lati ipele kan de omiran ni agbara lori idapada re gege bi O se bere re, ati mimu de ipele ikeyin ti i se Al – Jannah tabi Ina. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِن كُنتُمْ فِي رَيْبٍ مِّنَ الْبَعْثِ فَإِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ مِن مُّضْغَةٍ مُّخَلَّقَةٍ وَغَيْرِ مُخَلَّقَةٍ لِّنُبَيِّنَ لَكُمْ وَنُقِرُّ فِي الأَرْحَامِ مَا نَشَاء إِلَى أَجَلٍ مُّسَمًّى ثُمَّ نُخْرِجُكُمْ طِفْلاً ثُمَّ لِتَبْلُغُوا أَشُدَّكُمْ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّى وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَى أَرْذَلِ الْعُمُرِ لِكَيْلاَ يَعْلَمَ مِن بَعْدِ عِلْمٍ شَيْئًا وَتَرَى الأَرْضَ هَامِدَةً فَإِذَا أَنزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاء اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ وَأَنبَتَتْ مِن كُلِّ زَوْجٍ بَهِيجٍ * ذَلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّهُ يُحْيِي الْمَوْتَى وَأَنَّهُ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ {الحج 5/6}

“Eyin eniyan, ti eyin ba wa ninu iyemeji nipa ajinde, dajudaju, A se eda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa lati inu baasi eran ti o pe ni eda ati eyi ti ko pe ni eda, nitori ki A le se alaye (agbara Wa) fun yin. A si n mu ohun ti A ba fe duro sinu apo ibimo titi di gbedeke asiko kan. Leyin naa, A oo mu yin jade ni oponlo, Leyin naa, (e oo ma semi lo) nitori ki e le dagba, Eni ti o ma ku (ni kekere) wa ninu yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da (isemi) re si di asiko ogbo kojukujo nitori ki o fi ma le mo nnkan kan mo, leyiin ti o ti mo on, Ati pe wa ri ile ni gbigb, Nigba ti A ba si so ojo kale le lori, o ma yira pada. O maa gberu. O si maa mu awon orisirisi irugbin ti o dara jade * Iye ri bee nitori pe dajudaju Olohun ni Oba tooto, Dajudaju Oun ni O maa ji awon oku dide, Dajudaju Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan” (Suurah al – Hajj 5 – 6)

 Ibn Quayyim (Ki Olohun ke e) so pe: "Olohun ti mimo n se ti E so pe, ti e ba n se iyemiji nipa igbende, e ko si se iyemeji nipa pe eda ni yin, E ko si tun se iyemeji nibi bibere dida yin lati isesi kan de isesi miiran to fi de asiko ipele iku, igbende ti won se adehun re fun yin naa jo dida akooko ti e ko se iyemeji si, Bawo ni e se wa n tako ikan ninu iseda mejeeji, to si je pe e n ri afiwe re".

 Seyyid Qutbu (Ki Olohun ke e) so pe: "Awon ipele wonyi ti ole inu maa nkoja ni be ni ipele ipele, leyin naa yoo tun re koja de ipele omode leyin ti o ti ri imole, Eleyi n toka si pe Eni ti O nyi ipele yi pada ni Yio mu omoniyan losi ibi pipe re, a je wi pe omoniyan o le ri pipe ninu isemi ori – ile bi ko se pe, yoo koko duro na, leyin naa yoo pada, "Kofi le mo da nnkan kan mo mo, leyin ti o ti mo tele”, Kosi iyemeji wi pe ile ikeyin ni pipe omoniyan o ti pari daadaa. Itakosi awon ipele lori oro igbende leyin iku je itokasi kan to lepo mora won. O n toka si igbende labala kan pe eni ti o kapa dida ibere ni agbara lori didaapada. Itokasi iyen wa lori igbende tori pe Eni ti nyi awon ipele yi yio pe ipele omoniyan ni ile ikeyin. Bayi ni awon ibasepo dida eda ati pipada eda se ri, ti awon ibasepo isemi ati igbende se ri, ti ibasepo isiro – ise ati Esan naa si se ri. Gbogbo re patapata lo n seri si bibe Adeda, Oludari oro eda, Olukapa gbogbo nkan, ti kosi ariyanjiyan fun un".

  • Aisi aye ere fun sise eda. Wo oko Ayokele fun apeere, omoniyan ko se e, ko kan wa gbe jusile lasan ayafi idi ki o fi le mu anfaani pato wa. Nigba ti o se pe ere ni yio tumo si ninu opolo to ba je pe omoniyan se wahala losan, o si fi owo re sofo lori ise kan ti ko ri anfaani nibe, Se o wa ba opolo mu ki a so pe Eda omoniyan ti o tobi yii wa je eni ti won da lasan laini idi pataki bi? Woye si orike kan ninu awon orike ara re ti o je tinu ati t ode, o ri wi pe, won da a lati le mu nnkan pataki kan wa ni, ki ara re fi lagbara lati dide si mimu ohun ti a ti tori re da a wa, bakan naa igbende leyin iku naa wa, ko fi le je pe gbogbo emi kookan maa gba isiro ise ti o se ni. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لاَ تُرْجَعُونَ * فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ {المؤمنون 115/116}

“Se e lero pe A kan da yin fun iranu ni, ati pe eyin ko nii pada si odo wa?” * nitori naa, giga fun Olohun Oba Ododo, Ko si olohun miran ti ijosin to si afi Oun naa, Oluwa (to da) Ite Alaponle * Eni ti o ba pe olohun miiran mo Olohun, ko ni eri lowo lori re. dajudaju isiro – ise re si wa ni odo Oluwa re. dajudaju awon alaigbagbo ko nii jere” (Suurah al – Mu’miinuun: 115 – 116)

  • Ohun ti o fojuhan nipa oorun ati yiyaju sile fun eni ti o ba ronu jinle naa jo iku ati iye, oun naa ni jijade emi kuro lara leyin naa dida a pada si ara nigba keji, gege bi Olohun ti Ola Re ga se so:

"اللَّهُ يَتَوَفَّى الأَنفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَالَّتِي لَمْ تَمُتْ فِي مَنَامِهَا فَيُمْسِكُ الَّتِي قَضَى عَلَيْهَا الْمَوْتَ وَيُرْسِلُ الآخْرَى إِلَى أَجَلٍ مُسَمًّى إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ" {الزمر/42}

“Olohun ni O n gba awon emi ni akoko iku won ati (awon emi) ti ko nii ku si oju oorun won. O n mu (awon emi) ti O ti pase iku le lori mole. O si n fi awon yooku sile titi di gbedeke asiko kan, Dajudaju awon ami wa ninu iye fun ijo to ni arojinle” (Suurah a-z-Zumor):42)

 Al – Qurtobiyii so bayi nipa oro yii: "Oorun ati Iku won je ki awon mejeeji papo nibi jija kuro emi lara, ikan je ohun ti o han, eyi ti o han naa ni oorun, idi e niye ti won fi maa n so pe: Omo – iya iku ni oorun, Elekeji si je ohun ti o pamo, eyi ti o pamo naa ni iku, ki a wa kotan ki a so pe oorun naa ni Iku, Adape ni, ki i se papaa ohun ti o ri bee, fun bi awon mejeeji se papo nibi jija ti emi n ja kuro lara nibi ikini keji".

 Eni ti o n ji o, ti o n da emi pada si ara re, leyin oorun re, ni agbara lati da emi re pada si ara re leyin iku re, ati igbende re leyin iku, ododo loro Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba) ti o sope: " oorun ni omo iya iku, awon ara Aljunnah o si ni i sun”. (Sohiih, tobararaniy lo gba a wa. Sohiih Al – Albaniy 1086).

 

 

IPILE EDA ABARA NINU AL – QUR’AAN

            Ipile eda abara n seri si Anabi Adam (ki Ola Olohun ma ba a) eni ti Olohun ti ola Re ga da pelu owo re ti o da a dogba, ti o si fe emi si lara ninu emi re, ti o si ni ki awon malaika forikanle fun un ni ti aponle fun un. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلاَئِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِّن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ * فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُواْ لَهُ سَاجِدِينَ" {الحجر 28/29}

“(Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon Molaika pe: “Dajudaju Emi yoo se eda abara kan lati ara amo ti o dun kokoko, to ti pawoda. * Nigbati ti mo ba se e (ti o) gun rege tan, ti mo fe emi si (lara) ninu emi Mi (ti Mo da), nigba naa ki e wo lule fun un, leni ti yio fi orikanle” (Suurah al – Hijr: 28 – 29)

 Lehin naa, o da iyawo re Hawwau lati ara re, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَأَنزَلَ لَكُم مِّنْ الأَنْعَامِ ثَمَانِيَةَ أَزْوَاجٍ يَخْلُقُكُمْ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ خَلْقًا مِن بَعْدِ خَلْقٍ فِي ظُلُمَاتٍ ثَلاَثٍ ذَلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ لَهُ الْمُلْكُ لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ فَأَنَّى تُصْرَفُونَ" {الزمر/6}

“O se eda yin lati ara emi kan soso. Leyin naa O da iyawo re lati ara re. o si so mejo kale fun yin ninu eran – osin ni tako – tabo. O n se eda yin sinu iya yin, eda kan leyin eda kan ninu awon okunkun meta. Iyen ni Olohun, Oluwa yin. Ti Re ni ijoba, Ko si Olohun ti ijosin to si afi Oun naa. Nitori naa, bawo ni won tun se nse yin lori kuro nibi otito?” (Suurah a-z- Zumor: 6)

 Ki ofile je pe awon Aromodomo awon mejeeji ni won o pada gba ise rirole lori ile ti won o si mu ile duro, ni ibamu si ohun ti Olohun gba lero, ti o si fi rinle, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِي أَحْسَنَ كُلَّ شَيْءٍ خَلَقَهُ وَبَدَأَ خَلْقَ الإِنسَانِ مِن طِينٍ * ثُمَّ جَعَلَ نَسْلَهُ مِن سُلاَلَةٍ مِّن مَّاء مَّهِينٍ * ثُمَّ سَوَّاهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِن رُّوحِهِ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالأَبْصَارَ وَالأَفْئِدَةَ قَلِيلاً مَّا تَشْكُرُونَ" {السجدة7/9}

“Eni ti o se gbogbo nnkan ti O da ni daada. O si bere iseda eniyan lati inu erupe amo. * Leyin naa, O se awon aromodomo re lati ara ohun ti A mu jade lati ara omi kan ti o le. * Leyin naa, O to (orikereke) re ti ko fi sibi kan kan, O si fe (emi) si lara ninu emi re, O tun se igboro, iriran ati okan fun yin. Die ni ope ti e da” (Suurah a –s-Sajdah: 7-9)

 Gbogbo eda abara lapapo, lai se ayafi Kankan, pelu bi won se je pe orisirisi iran, orisirisi awo ati awon ipile orisirisi lo wa fun won, gbogbo won o maa seri si Anabi Adam (ki Ola Olohun maa ba a) eni ti o je ipile ati ibere won, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُواْ رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالاً كَثِيرًا وَنِسَاء وَاتَّقُواْ اللّهَ الَّذِي تَسَاءلُونَ بِهِ وَالأَرْحَامَ إِنَّ اللّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا" {النساء/1}

 “Eyin eniyan, eberu Oluwa yin, Eni ti O seda yin lati ara emi kan soso (iyen, Anabi Aadam). O si seda aya re (Hawaa) lati ara re. o fon opolopo okunrin ati obinrin jade lati ara awon mejeeji, Ki e si beru Olohun. Eni ti e fi n be ara yin (e so) okun – ibi. Dajudaju Olohun n je Oluso lori yin” (Suurah Nisaahi: 1)

Eleyi n toka si aini gbe ola fun eda abara Kankan lodo Olohun ayafi ki o sele ni ibamu si itele ase – Olohun won, tabi yiyapa ase Olohun won, Alijannah ni ibere ibugbe eda abara, Al – Qur’aan Alapon le so iroyin aponle ti Olohu ti mimo je ti E, ti Ola Re ga se fun Anabi Adam (Ki Ola Olohun maa ba a) ati ase ti Olohun pa awon Malaika re pe ki won teriba fun un, ati itan imulota ti esu mu un. Nigba ti o se motomoto, ti o sote, ti o si se keeta re lori ipo re ti Olohun gbe si, ti esu si ko lati teriba fun un, ni ti keeta sise, motomoto ati lilo agidi lati tele ase Olohun. O si seleri a ti mu jade kuro ninu Alujannah, lara keeta esu ti o le koko leyin ti ibinu Olohun tole koko ti han lori i re, ni pe o bura pe oun maa gbe ota sise jade si awon aromodomo re leyin re, o si na gbogbo agbara re ati gbogbo igbiyanju re lori ati so won nu, ki o fi le je pe iru adanwo to sele si oun maa sele si awon naa ninu iya Olohun ati ibinu Re. olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَقَدْ خَلَقْنَاكُمْ ثُمَّ صَوَّرْنَاكُمْ ثُمَّ قُلْنَا لِلْمَلآئِكَةِ اسْجُدُواْ لآدَمَ فَسَجَدُواْ إِلاَّ إِبْلِيسَ لَمْ يَكُن مِّنَ السَّاجِدِينَ * قَالَ مَا مَنَعَكَ أَلاَّ تَسْجُدَ إِذْ أَمَرْتُكَ قَالَ أَنَاْ خَيْرٌ مِّنْهُ خَلَقْتَنِي مِن نَّارٍ وَخَلَقْتَهُ مِن طِينٍ * قَالَ فَاهْبِطْ مِنْهَا فَمَا يَكُونُ لَكَ أَن تَتَكَبَّرَ فِيهَا فَاخْرُجْ إِنَّكَ مِنَ الصَّاغِرِينَ * قَالَ أَنظِرْنِي إِلَى يَوْمِ يُبْعَثُونَ * قَالَ إِنَّكَ مِنَ المُنظَرِينَ * قَالَ فَبِمَا أَغْوَيْتَنِي لأَقْعُدَنَّ لَهُمْ صِرَاطَكَ الْمُسْتَقِيمَ * ثُمَّ لآتِيَنَّهُم مِّن بَيْنِ أَيْدِيهِمْ وَمِنْ خَلْفِهِمْ وَعَنْ أَيْمَانِهِمْ وَعَن شَمَآئِلِهِمْ وَلاَ تَجِدُ أَكْثَرَهُمْ شَاكِرِينَ * قَالَ اخْرُجْ مِنْهَا مَذْؤُومًا مَّدْحُورًا لَّمَن تَبِعَكَ مِنْهُمْ لأَمْلأنَّ جَهَنَّمَ مِنكُمْ أَجْمَعِينَ * وَيَا آدَمُ اسْكُنْ أَنتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ فَكُلاَ مِنْ حَيْثُ شِئْتُمَا وَلاَ تَقْرَبَا هَذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الظَّالِمِينَ * فَوَسْوَسَ لَهُمَا الشَّيْطَانُ لِيُبْدِيَ لَهُمَا مَا وُورِيَ عَنْهُمَا مِن سَوْءَاتِهِمَا وَقَالَ مَا نَهَاكُمَا رَبُّكُمَا عَنْ هَذِهِ الشَّجَرَةِ إِلاَّ أَن تَكُونَا مَلَكَيْنِ أَوْ تَكُونَا مِنَ الْخَالِدِينَ * وَقَاسَمَهُمَا إِنِّي لَكُمَا لَمِنَ النَّاصِحِينَ * فَدَلاَّهُمَا بِغُرُورٍ فَلَمَّا ذَاقَا الشَّجَرَةَ بَدَتْ لَهُمَا سَوْءَاتُهُمَا وَطَفِقَا يَخْصِفَانِ عَلَيْهِمَا مِن وَرَقِ الْجَنَّةِ وَنَادَاهُمَا رَبُّهُمَا أَلَمْ أَنْهَكُمَا عَن تِلْكُمَا الشَّجَرَةِ وَأَقُل لَّكُمَا إِنَّ الشَّيْطَآنَ لَكُمَا عَدُوٌّ مُّبِينٌ * قَالاَ رَبَّنَا ظَلَمْنَا أَنفُسَنَا وَإِن لَّمْ تَغْفِرْ لَنَا وَتَرْحَمْنَا لَنَكُونَنَّ مِنَ الْخَاسِرِينَ * قَالَ اهْبِطُواْ بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ وَلَكُمْ فِي الأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَى حِينٍ * قَالَ فِيهَا تَحْيَوْنَ وَفِيهَا تَمُوتُونَ وَمِنْهَا تُخْرَجُونَ" {الأعراف11/25}

“Dajudaju A da yin, leyin naa A ya aworan yin, leyin naa A so fun awon molaika pe “E fori kanle ki Aadam”. Won si fori kanle ki, ayafi ‘Iblisi ti ko si ninu awon oluforikanle * (Olohun) so pe: “Ki ni o ko fun o lati fori kanle ki i nigba ti Mo pa o lase fun ” (Esu) wi pe: “Emi dara ju u lo, Ina ni O fi da emi, O si da oun lati ara erupe amo* (Olohun) so pe: “Sokale kuro nibi nitori pe ko letoo fun o lati segberaga nibi, Nitori naa jade, dajudaju iwo n be ninu awon eni yepere * (Esu) wi pe: Lo mi lara titi di ojo ti won yoo gbe (awon eniyan) dide” * (Olohun) so pe: Dajudaju iwo n be ninu awon ti A oo lo lara” *(Esu) wi pe: “fun wi pe O ti fi mi sinu anu, emi yoo jokoo de won ni ona Re taara. * Leyin naa, Dajudaju emi yoo wa ba won lati iwaju won, ati lati eyin won, ati lati otun won ati osi won, Iwo ko si ni ri opolopo won ni oludupe (fun O)”. * (Olohun) so pe: Jade kuro nibi (ki o si di) alabuku, eni – aledanu. Dajudaju enikeni ti o ba tele o ninu won, dajudaju Emi yoo fi gbogbo yin kun inu ina jaanamo”. * iwo Aadam, ki iwo ati iyawo re maa gbe ninu Ogba Idera. Nitori naa, e ma aje nibikibi ti e ba fe, Ki e si maa se sunmo igi yii nitori ki e maa ba wa ninu awon alabosi. * Esu si ko royiroyi ba awon mejeeji nitori ki o le fi ohun ti A fi pamo ninu ihoho ar a won han won. O si wi pe: “Oluwa eyin mejeeji ko ko igi yi fun yin bi ko se pe ki eyin mejeeji ma baa di molaika tabi ki eyin mejeeji maa baa di olusegbere”. * O si bura fun awon mejeeji pe: “Dajudaju emi wa ninu awon onimoran fun eyin mejeeji.” * O si tan awon mejeeji je, Nigba ti awon mejeeji to igi naa wo tan, ihoho awon mejeeji si han sira won. Won ba bere si fi awon ewe Ogba Idera bora won. Oluwa awon mejeeji sipe won pe: Nje Emi ko ti ko igi naa fun eyin mejeeji? (Se) Emi ko si ti so fun eyin mejeeji pe ota ponbele ni Esu je fun yin?” * Awon mejeeji so pe: “Oluwa wa, awa ti se abosi sira wa. Ti Iwo ko ba forijin wa, ki O si saanu wa, dajujdau awa yoo di ara awon eni ofo” * (Olohun) so pe: E sokale ota ni apa kan yin je si apa kan, Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin ni ori ile fun igba (die) * (Olohun) so pe: “Ni ori ile ni eyin yoo ti maa semi, ibe ni eyin yoo ma ku si, A o si mu yin jade lati inu re”. (Suurah Al ‘aa’raaf 11: 25)

 Gege bi eda abara ti Olohun da wa, ti a fi je aromodomo baba wa Adam, agbodo wa sora ki esu ma siwa lona, ti yoo fi wa mu wa jade kuro nibi titele ase Olohun, lo si bi iyapa ase Re, ti yoo si maa mu wa jade latinu igbagbo lo si bi aigbagbo, ayafi ki a ya ri pe a dimu sinsin iru nnkan ti Baba wa Adam (ki Ola Olohun maa ba a) duro le lori ninu imu – Olohun – lokan, ati gbigbe ijosin fun Olohun nikan, ki a si ripe a n fo emi wa mo kuro nibi ole jija, adisokan buburu ati keeta, ki a si je ki okan wa lalaafiaa si ara wa, ki a si gba Gbogbo ohun ti awon Ojise Olohun mu wa ninu awon ofin Olohun gbo, ki e si gbagbo pe ofin esin eyi ti Anabi Muhammad (ki Ike ati Ola maa ba a) ni ikeyin awon ofin – esin, ti o ye ki a gbagbo, ko fi le je pe a o so asiko ti esu o lo lati mu ileri aburu re se dofo, ileri aburu ti esu se nipa si si wa lona, ti ohun ti Olohun sadehun fun eni to ba tele esu o fi wa maa sele si wa, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قَالَ اخْرُجْ مِنْهَا مَذْؤُومًا مَّدْحُورًا لَّمَن تَبِعَكَ مِنْهُمْ لأَمْلأنَّ جَهَنَّمَ مِنكُمْ أَجْمَعِينَ" {الأعراف/18}

“(Olohun) so pe: Jade kuro nibi (ki o si di) alabuku, eni – adanu, Dajudaju enikeni ti o ba tele o ninu won, dajudaju Emi yoo fi gbogbo yin kun inu ina Jahanamo”. (Suurah Al ‘aa’raaf:18)

 

 

TAANI A N PE NI OMONIYAN?

 Eniyan naa ni Adam, ati iyawo re Hawwau, (Ki Ola Olohun maa baa won mejeeji) ati gbogbo ohun ti o jade lara awon mejeeji ni orisirisi iran eda abara, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُواْ رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالاً كَثِيرًا وَنِسَاء وَاتَّقُواْ اللّهَ الَّذِي تَسَاءلُونَ بِهِ وَالأَرْحَامَ إِنَّ اللّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا" {النساء/1}

“Eyin eniyan, e beru Oluwa yin, Eni ti O seda yin lati ara emi kan soso (iye, Anabi Aadam), O si seda aya re (Hawaa) lati ara re, O fon opolopo okunrin ati obinrin jade lati ara awon mejeeji, Ki e si beru Olohun, Eni ti e fi n be ara yin. (E so) okun – ibi. Dajudaju Olohun je Oluso lori yin” (Suurah Nisaahi: 1)

 Olohun sa omoniyan lesa laarin awon eda re, O se eda re lona to dara, O gbee duro, O si da ni aworan to dara ju, O si pe ni isesi julo. Olohun ti Ola Re ga julo so pe:

"لَقَدْ خَلَقْنَا الإِنسَانَ فِي أَحْسَنِ تَقْوِيمٍ" {التين/4}

“Dajudaju A da eniyan pelu irisi ti o dara ju lo” (Suurah a-t-Tiin: 4)

 Olohun si fi ohun ti a fi n da nnkan mo, awon orikerike ati awon adamo kan ta a lore. Ore ti temi ati ore ti laakaye, ti yo fi le lagbara lati se iyato laarin daadaa ati aida, ati lati mo pe dida daadaa eleyi ti won da a je ohun ti o ri bee ki o fi le gbo agboye ohun ti Olohun yoo so kale fun un ninu awon ise ti yoo fi ranse, ati mimu awon nkan to je dandan fun un ninu esin ati ninu awujo wa, ko fi le ni agbara ati le gbe papa pelu Gbogbo ohun ti o kojo sile aye to fe yii, ti yoo fi le ro fun awon nkan ti o maa se lanfaani titi aye, Dida ti olohun (ti mimo n be fun ti Ola Re si ga) da omoniyan latibi ara emi ati opolo je ohun ti Olohun so nipa re bayii:

"اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الأَرْضَ قَرَارًا وَالسَّمَاء بِنَاء وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَرَزَقَكُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ ذَلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ فَتَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ" {غافر/64}

“Olohun ni Eni ti O se ile fun yin ni ibugbe. O mo sanmo (le yin lori). O ya aworan yin. O si ya aworan yin daradara. O pese arisiki fun yin lati ara nnkan to dara. Iye ni Olohun, Oluwa yin. Nitori naa, mimo fun Olohun, Oluwa gbogbo eda”

(Suurah Goofir: 64)

 Olohun ti Ola Re ga tun so pe:

"خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ بِالْحَقِّ وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ" {التغابن/3}

“O da awon sanmo ati ile fun idi pataki. O ya aworan yin. O si se awon aworan yin daradara. Odo Re si ni abo eda” (Suurah at-T-Tagoobun: 3)

 Gbogbo ikookan ohun ti O ko jo sile aye yii loni ounje ti e, ti o si je pe koni le semi ayafi ki o ri i.

 

  • E o ri ARA:

 ohun ni ohun ti o gbe omoniyan duro, atunse re si ni imototo re ati imora re, pipe ojukokoro re ati adamo re yio maa sele nibi ohun jije ohun mimu ati fife iyawo tabi nini oko. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا بَنِي آدَمَ خُذُواْ زِينَتَكُمْ عِندَ كُلِّ مَسْجِدٍ وكُلُواْ وَاشْرَبُواْ وَلاَ تُسْرِفُواْ إِنَّهُ لاَ يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ * قُلْ مَنْ حَرَّمَ زِينَةَ اللّهِ الَّتِيَ أَخْرَجَ لِعِبَادِهِ وَالْطَّيِّبَاتِ مِنَ الرِّزْقِ قُلْ هِي لِلَّذِينَ آمَنُواْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا خَالِصَةً يَوْمَ الْقِيَامَةِ كَذَلِكَ نُفَصِّلُ الآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ {الأعراف 31/32}

 “Eyin omo (Anabi) Aadam, e wo (aso) oso yin nigbakigba ti e ba n lo si mosalasi, E maa je, ki e si maa mu, ki e si ma se lo ilo apa, Dajudaju (Olohun) ko nife awon onilokulo. *So pe: “tani eni ti yio se oso Olohun ti O mu jade fun awon erusin Re leewo, ati awon ije imu ti o dara? Sope: o je ti tawon ti won ni igbagbo ni isemi aye, yio si maa je ti won nikan ni ojo igbende, bayi ni A se maa se alaye ni ifosiwewe fun awon ijo ti won ni imo” (Suurah Al – ‘a – raaf: 31- 32)

 Olohun si pa lase pelu titoju ara lasiko to ba n se aisan, ati amodi pelu lilo orisirisi awon ogun aisan to leto. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: "Dajudaju Olohun ti so aisan ati oogun kale, o si ti fi oogun le le fun gbogbo aisan kookan, nipa bayii, e maa se oogun si aisan sugbon e ma fi nnkan eewo se oogun o". (Hadith yii ni alaafia)

 Gbigbo bukata ibalopo laarin toko-taya ni ibamu si ofin Olohun, ki o mo fid a gege bi awon eranko. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِّتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ" {الروم/21}

 “O wa ninu awon ami Re pe: O seda awon aya fun yin lati ara yin nitori ki e le ri ifayabale ni odo won. O si fi ife ati ike si aarin yin. Dajudaju awon amin wa ninu iyen fun ijo to ni arojinle” (Suurah a-r-Ruum: 21)

 

  • Emi:

 Ohun ti o n gbe emi ro, ti emi fi n je alaaye, ti o si tun je ounje re ni igbagbo si eledaa re, riropo mo si sin.In, gbigbe ara le E, titele ase Re. pelu sise ohun ti a se ni dandan fun emi, gbigbe ju sile ohun ti o ko fun un, nitori wiwa bukata re si odo eleda re, nibi igbagbo ni yio ti ri ifokanbale, ti yio si ti ni isinmi, ti yi o si maa se daada, ti yio si maa dunnu, ti yio maa jere, ti yio si maa gbadun, pelu igbagbo naa si tun ni yi o fi maa moribo nibi ipaya ati idaamu ti yio ni oripa buruku ninu ara, ti yio si ko iparun ba ara. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الَّذِينَ آمَنُواْ وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُم بِذِكْرِ اللّهِ أَلاَ بِذِكْرِ اللّهِ تَطْمَئِنُّ الْقُلُوبُ {الرعد/28}

“Awon ti won gbagbo ni ododo, ti awon okan won si n bale pelu iranti Olohun, e gbo o! okan yio maa bale pelu iranti Olohun" (Suurah a-r-Ra’d: 28)

 

  • LAAKAYE (OPOLO)

Islam gbe ipo opolo ga, o si fun omoniyan ni ominiran to peye nibi ironu si gbogbo ohun ti won ba pa lase. Nipa bayi ko ni ti ni adisokan nkankan ayafi leyin igba ti o ba ni itelorun ati iyonu lori re, ko ni i ti gba ofin kan ni ilana ninu isemi re ayafi leyin arojinle ti yio fi le mo boya ofin naa ni alaafia.

Eleyi ni ohun ti Olohun fi sesa omoniyan yato si elomiran ninu awon eda, pelu opolo si ni awujo fi maa n dagbasoke, ti o si fi maa n tesiwaju, ti omoniyan si fi maa n lagbara ati sanfaani pelu gbogbo ohun ti o yi i ka bii sanmo, ile, ibudo, yio si lo lati se isemi re daada, opolo ni yoo fi mo iwa ti o dara, ti isesi o fi maa duro deede, ti awon agboye o si fi maa dagabsoke, ti awon awujo o fi maa lo letoleto, pelu opolo ni won fi maa n mo ododo ati iro, daadaa ati aida, ohun to sanfaaani ati ohun to mu inira lowo, ohun si ni okunfa fun siso ofin esin di dandan fun eniyan ninu Islaam, ninu deede Olohun ti o mo julo ti o si ga julo ni pe won o ni se isiro fun omoniyan ayafi ki o je pe ipase opolo ni won o fi se e, eni ti ko ba ni laakaye, ti kosi mo otun yato si osi, ninu ofin esin Islaam, kosi ninu eni ti won wa lati se nnkan tabi ki o wa ninu eniti won yoo se isiro ise fun, tori idi eyi ni Islaam se pase siso opolo, Ti o si se ofin Ibawi laye ati iya lorun fun eni ti o ko inira ba laakaye re , ti o si fun awon ojukokoro re pelu mimu oti ati awon nkan ti n muni hunrira, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالأَنصَابُ وَالأَزْلاَمُ رِجْسٌ مِّنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ" {المائدة/90}

 “Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju oti ati tete ati orisa ati ise yiyewo, egbin ni ninu ise Esu, Nitori naa, e jinna si i nitori ki e le jere” (Suurah al – Moo’idah: 90)

 Olohun ti se iroyin eni ti o so laakaye dole pelu erongba re, ti o se arojinle ati ikomimo ni eewo fun, pe ipo awon eran – osin ni won wa, ti kosi ironu fun won koja ounje, ohun mimun ati ibalopo ako ati abo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ شَرَّ الدَّوَابَّ عِندَ اللّهِ الصُّمُّ الْبُكْمُ الَّذِينَ لاَ يَعْقِلُونَ" {الأنفال/22}

“Dajudaju eda ti o buru ju lo ni odo Olohun ni awon aditi, oyaya ti ki se laakaye” (Suurah Al-Anfaal: 22)

 Laakaye yii naa ni ounje ti e, eleyi ti o je pe pelu re ni o fi maa n ga si, ti awon onje yi o maa sele lati ara:

ALAKOOKO: Mimo

            Olohun ti o mo julo, ti Ola Re ga, ti ro opolo yii lagbara, eyi ti n jeyo nibi gbigbo, riri, gbigbo oorun, dida nnkan mo, latara awon wonyi ni opolo se n lagbara lati jeun, ati riri idagbasoke pelu gbogbo orisirisi imo, ki o fi le gbe aye, ati ki gbogbo ohun ti o wa laye fi ro fun atunse re, latara ohun ti o maa mu ki opolo le da nnkan mu wa, ti o si le mu idagbasoke ba a, ki o fi le se daada nibamu si isemi re. olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَاللّهُ أَخْرَجَكُم مِّن بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ لاَ تَعْلَمُونَ شَيْئًا وَجَعَلَ لَكُمُ الْسَّمْعَ وَالأَبْصَارَ وَالأَفْئِدَةَ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ" {النحل/78}

 “Olohun ni O mu yin jade lati inu ikun awon iya yin (nigba ti) eyin ko ti da nnkan kan mo, O si fun yin ni igboro, iriran ati awon okan nitori ki e le maa dupe (fun – un)” (Suurah a-n-Nahl: 78)

Tori idi eyi, ni Islaam fi se agbega lori oro imo ati awon onimimo, o si se iyato laarin onimimo ati Alaimokan, gegebi Olohun ti Ola Re ga se salaye pelu oro Re yii:

"قُل هَلْ يَسْتَوِي الَّذِينَ يَعْلَمُونَ وَالَّذِينَ لاَ يَعْلَمُونَ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُوْلُوا الأَلْبَابِ" {الزمر/9}

“Nje awon ti won nimo ati awon ti ko nimo dogba bi? Awon onilaakaye nikan ni won n lo isiti” (Suurah a-z-Zumor: 9)

 Nigba ti Islaam se wiwa imo ni ara awon ohun asunmo to se pe yio sun eniyan mo Olohun ti Ola Re ga, ni pataki julo, awon imo ti yio seri anfaani si eda abara, tori idi eyi ni awon onimimo, ti won je Musulumi ninu awon eni akooko fi maa nse idije nibi wiwa imo, eyi ti abajade re je ohun ti o sokunfa fifon imo kaakiri lagbaye, ti olaju aye ode – oni si duro le lori. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَرْفَعِ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا مِنكُمْ وَالَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ دَرَجَاتٍ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ" {المجادلة/11}

“Olohun yoo se agbega awon ipo fun awon ti won ni igbagbo ododo ati awon ti A fun ni imo ninu yin. Olohun si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise”

 (Suurah al–Mujaadalah: 11)

 

ELEEKEJI: Arojinle

            Awon ibi ti a ti maa n lo ironu fe gan, tori pe ohun ni idaraya fun opolo, ati itura fun emi, yio wa dawa fun ara re, yio wa fun laakaye ni ijanu nipa ile aye to fe gan yii, ki o fi le ro arojinle lori gbogbo ohun ti Olohun je ki o maa be nile aye, laarin awon iseju aaya die, emi to mo, ati opolo toye, yio ti da papa aye yi mo, aye ti ki i se pe oun lo da ara re, kosi je pe oun lo da nnkan ninu iran ara re, won o si ri afijo re miran, laisi iyemeji, a n bowa mu itokasi wa lori eledaa re. olohun ti Ola re ga so pe:

"أَوَلَمْ يَنظُرُواْ فِي مَلَكُوتِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَمَا خَلَقَ اللّهُ مِن شَيْءٍ وَأَنْ عَسَى أَن يَكُونَ قَدِ اقْتَرَبَ أَجَلُهُمْ فَبِأَيِّ حَدِيثٍ بَعْدَهُ يُؤْمِنُونَ" {الأعراف/185}

 “Se won ko woye si ijoba awon sanmo ati ile pelu gbogbo nnkan ti Olohun da? o le je pe Akoko opin aye won ti sunmo, Nigba naa, oro wo ni won yoo ni igbagbo ninu re leyin re?” (Suurah Al – a’raaf: 185)

 Ironu ati Arojinle wa ninu awon ijosin to lola ninu Islaam, nigba ti opolopo Ayat Al – Qur’aan pepe si i, Olohun maa fe ki awon erusin OUN ni iwoye, lo fa to fi maa n so pe:

"أَفَلاَ يَنْظُرُونَ"

"Se won o ni woye ni?"

Nipa ironu, Olohun maa n so pe:

"أَوَ لَمْ يَتَفَكَّرُوا"

"se won o ronu ni?"

Nipa iranti, Olohun maa n so pe:

"أَفَلَا تَذَكَّرُونَ"

"se won o se iranti ni?"

Npa opolo, Olohun so pe:

"أَفَلَا تَعْقِلُونَ"

"nje e o ni se laakaye ni?"

Nipa Rironu si awon nnkan ti a n ri:

"أَوَ لـَمْ يَرَوْا "

                                     "nje won o rii ni?"

 Gbogbo agbekale yii waye ni tori amuse ero ti I se eri lori bibe Olohun ati titobi Olohun, lara awon Ayat wonyi niyi:

 Pipe ironu si awon idekun Olohun ti a fi n semi laye, eleyi ti Olohun da fun wa, ti Olohun si fi se idekun fun wa, Olohun ti Ola re ga so pe:

"وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ إِذَا أَنتُم بَشَرٌ تَنتَشِرُونَ * وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِّتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ * وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَاخْتِلاَفُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّلْعَالِمِينَ * وَمِنْ آيَاتِهِ مَنَامُكُم بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَابْتِغَاؤُكُم مِّن فَضْلِهِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ * وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاء مَاء فَيُحْيِي بِهِ الأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ * وَمِنْ آيَاتِهِ أَن تَقُومَ السَّمَاء وَالأَرْضُ بِأَمْرِهِ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِّنَ الأَرْضِ إِذَا أَنتُمْ تَخْرُجُونَ" {الروم20/25}

“O wa ninu awon ami Re pe, O seda yin lati ara erupe. Leyin naa ni e ba di abara ti e n fonka (si ori ile aye). * O wa ninu awon ami Re pe, O seda awon aya fun yin lati ara yin nitori ki e le ri ifayabale ni odo won, O si fi ife ati ike si aarin yin, Dajudaju awon ami wa ninu iye fun ijo to ni arojinle. * O wa ninu awon ami Re, dida awon sanmo ati ile ati okan – o jokan awon ede yin ati awon awo ara yin, Dajudaju awon ami wa ninu iye fun awon onimimo. * Ninu awon ami Re ni oorun yin ni ale ati ni osan, ati bi e se n wa ninu oore Re (fun ije – imu), Dajudaju awon ami wa ninu iye fun ijo ti n gboro (otito). * Ninu awon ami Re tun ni fifi monamona han yin ni ti eru ati ireti, O si n so omi kale lati sanmo, O fi n ta ile ji leyin ti ile ti sa. Dajudaju awon ami wa ninu iye fun ijo to ni laakaye. * Ninu awon ami Re tun ni pe sanmo ati ile duro pelu ase Re, Leyin naa, nigba ti O ba pe yin ni ipe kan nigba naa ni eyin yoo maa jade lati inu ile” (Suurah ar-Ruum: 20 – 25)

  • Ipepe si rironu si awon igi to wa legbe ara won wonyi, eleyii ti o se ori – ile kansoso naa ni gbogbo won wa, ti won si maa n fun won lomi kannaa mu, ati ounje kan naa, sugbon ti won o wa yapa nibi awon eso ti o maa jade lara won. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَفِي الأَرْضِ قِطَعٌ مُّتَجَاوِرَاتٌ وَجَنَّاتٌ مِّنْ أَعْنَابٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَى بِمَاء وَاحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَى بَعْضٍ فِي الأُكُلِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ {الرعد/4}

 “O tun wa ninu ile awon abala –abala ile (Oniiran – ran) to wa nitosi ara won ati awon ogba oko inab, ati irugbin ati igi dabidun eleka ati alaileka, Omi kan naa si ni won n fun won (mu), A tun se ajulo fun apa kan re lori apa kan nibi eso, Dajudaju awon amin wa ninu iye fun ijo to ni laakaye” (Suurah a-r-R’ad: 4)

 Ipepe si rironu si awon emi to wa lara, ati bi awon emi se n gunra won, kikojo emi, ati awon nnkan to kojo sinu re ninu awon orikerike kan ti o gbe e duro, eleyi ti omoniyan kagara nibi sise e re, koda ki won o kojo papa. Olohun ti Ola Re ga sope:

"وَفِي الأَرْضِ آيَاتٌ لِّلْمُوقِنِينَ * وَفِي أَنفُسِكُمْ أَفَلاَ تُبْصِرُونَ * وَفِي السَّمَاء رِزْقُكُمْ وَمَا تُوعَدُونَ {الذاريات 20/22}

 “Awon ami wa ni ori ile fun awon alamodaju * Ninu ara yin gan – an (ami wa ninu re) Se eyin ko riran ni? * Arisiki yin ati ohun ti A n se ni adehun fun yin wa ni sanmo” (Suurah a-th-Thariyyaat: 20 -22)

  • Ipepe si ironu si awon kokor o won yi ti won n rokirika wa, ti won si n ba wa gbe ni ile aye yii, ati awon anfaani ti n waye lati ibi awon kokoro kan fun eda abara. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَأَوْحَى رَبُّكَ إِلَى النَّحْلِ أَنِ اتَّخِذِي مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا وَمِنَ الشَّجَرِ وَمِمَّا يَعْرِشُونَ * ثُمَّ كُلِي مِن كُلِّ الثَّمَرَاتِ فَاسْلُكِي سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلاً يَخْرُجُ مِن بُطُونِهَا شَرَابٌ مُّخْتَلِفٌ أَلْوَانُهُ فِيهِ شِفَاء لِلنَّاسِ إِنَّ فِي ذَلِكَ لآيَةً لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ" {النحل 68/69}

 “Oluwa re si fi mo kokoro oyin pe: Maa kole sinu apata ati igi ati ohun ti (awon eniyan) mo ga * Leyin naa, maa je lara gbogbo eso, ki o si maa to awon oju ona Oluwa pelu iteriba, Ohun mimu ti awo re yato sira won yoo ma jade lati inu (kokooro oyin), Iwosan ni fun awon eniyan, Dajudaju amin wa ninu iye fun ijo to ni arojinle” (Suurah a-n—Nahl: 68 - 69)

  • Ipepe si ironu si eranko wonyi, ti won n gbe pelu wa, ti Olohun si ro won fun wa ki a maa je ninu won, ki a maa mu, ki a si maa gun ninu won. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِنَّ لَكُمْ فِي الأَنْعَامِ لَعِبْرَةً نُّسْقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهِ مِن بَيْنِ فَرْثٍ وَدَمٍ لَّبَنًا خَالِصًا سَآئِغًا لِلشَّارِبِينَ * وَمِن ثَمَرَاتِ النَّخِيلِ وَالأَعْنَابِ تَتَّخِذُونَ مِنْهُ سَكَرًا وَرِزْقًا حَسَنًا إِنَّ فِي ذَلِكَ لآيَةً لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ" {النحل/67}

“Ati pe ariwoye wa fun yin lara awon eran osin, A n fun yinni wara mimo mu, ti n lo garagara fun awon ti n mu u, ninu ohun ti n be ninu iku re, laarin igbe ati eje, * Ati pe lati ara awon eso dabidun ati eso ajara ni e ti n se oti ati ije-imu to dara, Dajudaju ami wa ninu iye fun ijo to ni laakaye” (Suurah a-n-Nahl: 66-67)

  • Ipepe si rironu si awon nnkan ti o n fo loju sunmo ninu awon eye wonyi, lori bi Olohun se ro ofurufu fun un ki o fi le je pe yio dara fun fifo re, ti Olohun si da awon iye mo won, ki won o fi lagbara ati le gbe iye naa soke sona sanmo, to si je pe omoniyan o lagbara lati fo bee, ti Olohun ba fun un ni awon iye ti yoo fi fo. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَلَمْ يَرَوْاْ إِلَى الطَّيْرِ مُسَخَّرَاتٍ فِي جَوِّ السَّمَاء مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلاَّ اللّهُ إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ" {النحل/79}

“Se won ko woye si awon eye ti A te lori ba (lati maa fo kiri) ninu ofurufu (ni abe) sanmo? Ko si eni ti o mu won duro (sinu ofurufu) bi ko se Olohun. Dajudaju awon amin wa ninu iye fun ijo to ni igbagbo ododo". (Suurah a-n-Nahl:79)

 Seyyid Qutub (ki Olohun ke e) sope: "sugbon, ronu jinle si oro eye, ti o maa n na iye mejeeji re, ti o si ma an kaa pada, leyin naa yio pa awon iye re mejeeji yii mora, yio si wa ninu awon isesi meji, Isesi nina iye fun fifo tan yanyan, ati isesi pipa iye mora ti yio si tun wa ninu ofurufu. O si maa n fo nibe ni fifo kan to rorun, ti o si nlo ni pelepele. Nigba miiran a si maa se awon isesi kan ti yio dabi idan loju oluworan, fun gbigbe ra ati fifosoke. Ronu daadaa si ohun ti a n ri, ki O si fi oju re tele gbogbo okookan awon eye nibi lilo bibo wo pelu iran okookan won.

 Wiwo (awon eye) ko le su eniyan, okan naa o si le ko susu. Igbadun kan lo je, to koja ohun ti ironu ati Arojinle le mu wa, eda Olohun toje ti iyanu. Eleyi ti pipe ati ewa pe sibe, Al – Qur’aan n pepe si wiwoye si eleyi, ko si ohun ti o diwon mu ayafi pelu agbara Olohun Ajoke aye, akiyesi maa n be nibe fun tomode ati ohun ti o kere jojo, Mimu eye duro ni ofurufu da gege bi mimu awon daba orile naa duro ni.

Bi eye se maa n se ninu odan naa si dabi imuduro Gbogbo nnkan, eyi ti o se pe kosi eni ti o mu duro laaye re bi ko se Olohun.

  • Ipepe si ironu nipa awon agbaye to wa laye yii patapata, ile re, sanmo re, ati gbogbo ohun ti Olohun da sinu awon mejeeji ati laarin mejeeji, ninu awon daba, ati ona ti Olohun gba dawon ati eto isemi won. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَاللَّهُ خَلَقَ كُلَّ دَابَّةٍ مِن مَّاء فَمِنْهُم مَّن يَمْشِي عَلَى بَطْنِهِ وَمِنْهُم مَّن يَمْشِي عَلَى رِجْلَيْنِ وَمِنْهُم مَّن يَمْشِي عَلَى أَرْبَعٍ يَخْلُقُ اللَّهُ مَا يَشَاء إِنَّ اللَّهَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ" {النور/45}

 “Olohun se eda gbogbo abemi lati inu omi. O wa ninu won eyi ti n fi aya re wo O wa ninu won eyi ti n fi ese meji rin, O si wa ninu won eyi ti n fi merin rin, Olohun n se eda ohun ti O ba fe, Dajudaju Olohun ni Alagbara lori gbogbo nnkan.” (Suurah a-n-Nuur: 45)

 bawo ni Olohun se n pin awon Arisiki laarin awon daba ori ile, ti Arisiki kan si n yato si omiran ni ibamu si awon agbegbe okookan, ohun ti o dara fun iran kan, ko ni o dara fun iran miiran, nkan ti o dara gege bi ibugbe fun iran kan, ko ni dara fun ibugbe iran miiran. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا مِن دَآبَّةٍ فِي الأَرْضِ إِلاَّ عَلَى اللّهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ" {هود/6}

 “Ko si eda kan ti o wa ni ori ile afi ki o je pe Olohun ni Olupese arisiki re, O mo ibusun re ati ibugbe re, Gbgbo re ti wa ninu akosile ti o han kedere” (Suuratul Huud: 6)

 Ipepe si ironu si ipile eda omoniyan, ati awon ona jije -mimu re, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَفَرَأَيْتُم مَّا تُمْنُونَ * أَأَنتُمْ تَخْلُقُونَهُ أَمْ نَحْنُ الْخَالِقُونَ * نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ الْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ * عَلَى أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَالَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِي مَا لاَ تَعْلَمُونَ * وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ النَّشْأَةَ الآولَى فَلَوْلاَ تَذكَّرُونَ * أَفَرَأَيْتُم مَّا تَحْرُثُونَ * أَأَنتُمْ تَزْرَعُونَهُ أَمْ نَحْنُ الزَّارِعُونَ * لَوْ نَشَاء لَجَعَلْنَاهُ حُطَامًا فَظَلَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ * إِنَّا لَمُغْرَمُونَ * بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ * أَفَرَأَيْتُمُ الْمَاء الَّذِي تَشْرَبُونَ * أَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ الْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ الْمُنزِلُونَ * لَوْ نَشَاء جَعَلْنَاهُ أُجَاجًا فَلَوْلاَ تَشْكُرُونَ * أَفَرَأَيْتُمُ النَّارَ الَّتِي تُورُونَ * أَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَا أَمْ نَحْنُ الْمُنشِؤُونَ * نَحْنُ جَعَلْنَاهَا تَذْكِرَةً وَمَتَاعًا لِّلْمُقْوِينَ" {الواقعة 58/73}

“E o ri ato ti e n da jade (sinu apoduke)? * Se eyin ni e se eda re ni abi Awa ni A se eda re? * Awa ni A yan kadara (ojo) iku fun gbogbo yin, Awa ko si le kagara Lati yi irisi yin pada (kuro ni erupe), ki A si seda yin (fun Ajinde) pelu (irisi) ti e yin ko mo. * Dajudaju eyin nimo nipa iseda (yin) fun isemi aye (pe Emi ni mo da yin), nitori naa, ki ni ko je ki e lo isiti na? * E so fun Mi na nipa nnkan ti e n gbin sinu ile, * Se eyin ni e n je ki o hun jade ni abi Awa ni A n je ki o hu jade? * Ti a ba fe ni, Awa iba so o di gbigbe, eyin yo si maa seenmo. * (Eyin yo si wi pe:) “Dajudaju awa di onigbese.” * (Awon miiran yo si wi pe:) “Rara o! won se ikore oko ni eewo fun wa ni.” * Se eyin ni e n so o kale lati inu esujo ni abi Awa ni A n so o kale? * Ti A ba fe ni, Awa iba se e ni kikoro, Nitori naa, ki ni o fa a tie yin ko fi maa dupe? * E so fun Mi na nipa ina ti e n da, * se eyin ni e da igi re ni abi Awa ni A da a? * Awa se ina aye ni iranti (fun Ina orun) ati nnkan elo fun awon onirin – ajo". (suuratul waqihah:58-73)

 Tori idi eyi, ni Al – Qur’aan se bu awon ti ki i woye, ti ki i si i ronu, ti won ki n fi ohun ti won n ri se isiti fun ara won ni ile aye ti o fe gan yii, O si royin won pelu pe won o ni nkan ti won a fi da nnkan mo, nitori a i da eledaa won mo, ati a i mo idi ti won fi da won, nipa bayii, o fi won we eran – osin ti koni opolo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَقَدْ ذَرَأْنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرًا مِّنَ الْجِنِّ وَالإِنسِ لَهُمْ قُلُوبٌ لاَّ يَفْقَهُونَ بِهَا وَلَهُمْ أَعْيُنٌ لاَّ يُبْصِرُونَ بِهَا وَلَهُمْ آذَانٌ لاَّ يَسْمَعُونَ بِهَا أُوْلَئِكَ كَالأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ أُوْلَئِكَ هُمُ الْغَافِلُونَ {الأعراف/179}

“Dajudaju A da opolopo eniyan ati alujanna fun ina Jaanamo (nitori pe) won ni okan, won ko si fi gbo agboye, won ni oju, won ko fi riran, won ni eti, won ko si fi gboran. Awon wonye da bi eran – osin, Won wule sonu ju lo. Awon wonye ni afonu – fora” (Suurah Al-A‘raaf: 179)

 Sugbon Islam de ironu yii pelu enu – aala, eleyii ti o gbe eni ti o n ronu de ibi dida Olohun mo latari awon eda a re. nipa bayii, yoo wa duro lori enu aala yii, kosi gbodo koja re, pelu rironu ohun ti ko lagbara lori fife loju re, nitori pe eda ti Olohun da ni opolo je, o si ni enu aala nibi mimo awon nnkan, nipa bayii ko gbodo koja aala, eni ti o ba koja aala opolo re iru eni yi ti sabosi opolo re, o si ti se akoba fun un, apejuwe re da gege bi eni ti o gbe atupa to ni 110 fuett le ori atupa (bulb) ti agbara re je 220 feult, ohun ti o ye ni abajade eleyii.

 

 

SISE ESA TI OLOHUN SE AWON OMO ANABI ADAM

Laarin awon eda ti n be laye yii, eda abara ni Olohun ti o gbon – ngbon, ti o ga julo sa lesa, ti o si gbola fun ju awon eda yoku lo. Olohun ti Ola re ga so pe:

"وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِّمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلاً" {الإسراء/70}

 “Dajudaju A se aponle fun awon omo (Anabi) Aadam. A gbe won rin lori ile ati lori omi, A si fun won ni ije – imu ninu awon nnkan to dara, A si soore ajulu fun won gan – an lori opolopo ninu awon ti A da”. (Suurah al-Isroo: 70)

 Lara awon onan ti Olohun ti gbe aponle fun omo Anabi Adam ni wonyii:

 

1- RIRO ILE – AYE FUN UN:

Olohun ro aye yii fun omoniyan, ninu ohun ti O ro ni ile re, sanmo re, ati gbogbo nnkan ti o da sinu re ninu awon agbaye orisirisi ni riro kan to lola pupo, Olohun si pese re kofi le je ki isemi awon omoniyan yio dara, latari ohun ti o ko sinu re, ninu awon ohun ti o le mu ki isemi duro, bii; Afefe omi, awon ije – imu, awon eranko, awon igi ati awon irugbin Olohun si se won ni o n ti o ro fun omoniyan, won si n lo won n bo lori ile aye pelu ohun ti Olohun fi tawon lore ninu imo ti o si ti dawon lola ninu opolo, gege bi Ologun ti Ola re ga se royin pe:

"وَسَخَّرَ لَكُم مَّا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الأَرْضِ جَمِيعًا مِّنْهُ إِنَّ فِي ذَلِكَ لاَيَاتٍ لَّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ" {الجاثية/13}

 “O tun te lori ba fun yin ohun ti o wa ninu sanmo ati ohun ti o wa lori ile patapata lati odo ara Re. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo to ni arojinle”

(Suurah al-Jaathiyah: 13)

Olohun si pa won lase pe ki won o so orile aye won, ki won si lo o daadaa, ki won o si so oju ile – aye lori ile ati ni sanmo, ati ninu ibudo ko fi le je pe oju – ojo yio maa dara si i, ki won fo ile gbadun isemi ni aye ati awon miran ti n bo leyin won ninu eda abara, pelu pe Olohun ko fun ominiyan nipa biba ile je, tabi sise ibaje ninu e. olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تُفْسِدُواْ فِي الأَرْضِ بَعْدَ إِصْلاَحِهَا وَادْعُوهُ خَوْفًا وَطَمَعًا إِنَّ رَحْمَتَ اللّهِ قَرِيبٌ مِّنَ الْمُحْسِنِينَ" {الأعراف/56}

“E ma se ibaje lori ile leyin atunse re, ki e si ke Pe E pelu iberu ati sise agbokante, dajudaju aanu Olohun sunmo awon oluse daada” (Suurah Al-A‘raaf: 56)

 

2- JIJE AROLE LORI ILE

            Olohun se aponle fun eda abara, O si se won ni Arole lori ile, ti awon apa kan si n role fun apa miiran ni iran kan leyin iran kan, won ko si ja kuro nibi jijogun imo ati esin, ati ki ilana ijosin ti Olohun gbero nile aye yii le maa lo lori ile. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَهُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلاَئِفَ الأَرْضِ وَرَفَعَ بَعْضَكُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ لِّيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ إِنَّ رَبَّكَ سَرِيعُ الْعِقَابِ وَإِنَّهُ لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ" {الأنعام/165}

 “(Olohun) Oun ni Eni ti O se yin ni arole lori ile, O si fi onan ipo gbe yin ga ju ara yin lo nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yi. Dajudaju Oluwa re ni Oluyara nibi iya, Dajudaju Oun si ni Alaforijin, Alaanu” (Suurah al-Ani’aam: 165)

 Olohun wa se ile – aye yii ni ohun to lagbara, lati je itura fun won bakan naa ko le je itura fun gbogbo eda a Re nipa pe Olohun lo je olutoju awon Arisiki won ati onje won titi ti yoo fi yonda titan fun aye. Nipa pe Olohun so pe:

"قُلْ أَئِنَّكُمْ لَتَكْفُرُونَ بِالَّذِي خَلَقَ الأَرْضَ فِي يَوْمَيْنِ وَتَجْعَلُونَ لَهُ أَندَادًا ذَلِكَ رَبُّ الْعَالَمِينَ * وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ مِن فَوْقِهَا وَبَارَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَا أَقْوَاتَهَا فِي أَرْبَعَةِ أَيَّامٍ سَوَاء لِّلسَّائِلِينَ" {فصلت9/10}

 “So pe: “Nje dajudaju eyin n saigbagbo ninu Eni ti O da ile fun ojo meji, e si n so (eda Re) di egbera fun Un?” Iye si ni Oluwa gbogbo eda. * O si fi awon apata sinu ile, lati oke re, O si pebubu awon onje (ori ile fun eda) laaarin ojo merin, deede ni fun awon ti won ba beere (nipa re)” (Suurah goofir: 9 – 10)

 

3- AJOSE ATI IKOJOPO

            Olohun ti Ola re ga da eda abara, O si se won fonwonka si orisirisi aye lori ile, fun ogbon kan ti Olohun gbero funra re, Olohun si se won ni orile – ede ati iran – iran gbogbo eni kookan won lo si ni isesi adamo ti e, ise ajogunba ti e, ede ti e, irisi ti e, ni titori ki won fi le mo da ara won mo laarin ara won, ki won si maa fi anfaani daadaa titi aye ati tesin paaro fun ara won, Olohun ko da won, ki won fi maa mu ara won lota, ki won si fi maa ji dukia ara won, ki abala kan si ma maa mu abala miiran ni eru, gege bi Olohun ti Ola Re ga ti O sigbon – ngbon ti se royin bayii:

"يأ أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَى وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ {الحجرات/13}

 “Eyin eniyan, dajudaju A da yin lati ara okunrin ati obinrin, A si se yin ni orile – ede orile – ede ati iran – iran nitori ki e le mo ara yin, Dajudaju eni ti o ni aponle ju lo ninu yin ni odo Olohun ni eni ti n paya (Re) ju lo, Dajudaju Olohun ni Olumo, Alamotan” (Suurrah al – Hujuroot: 13)

 Nipa bayii, Olohun da ile ni n ti okan n dara ju omiran lo, nipa ohun ti n jade ninu re, ati oore inu re, gege bi Olohun se da awon eda abara lorisirisi nipa agbara won, opolo won ati irisi won, nnkan ti eniyan ba ri lodo awon ara orile – ede kan ko ni yoo ri lodo awon ara orile – ede miiran ninu awon nnkan to dara, gbogbo re ko sa dede ri bee bi ko se pe nitori a ti le da ara wa mo, ki a si jo mo ba ara wa se, ki a si jo maa kojo po lori awon nnkan ti yio je ki gbogbo nnkan maa dara si, nipa bayii, awon nkan anfaani yio maa di lilo lati ibikan si ibomira, ti dida ara eni yio di ohun ti a o maa paaro sira won, ti iranlowo ti o maa lo gbere o si maa sele laarin won, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَهُمْ يَقْسِمُونَ رَحْمَةَ رَبِّكَ نَحْنُ قَسَمْنَا بَيْنَهُم مَّعِيشَتَهُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَرَفَعْنَا بَعْضَهُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ لِيَتَّخِذَ بَعْضُهُم بَعْضًا سُخْرِيًّا وَرَحْمَتُ رَبِّكَ خَيْرٌ مِّمَّا يَجْمَعُونَ" {الزخرف/32}

“Se awon ni won maa pin ike Oluwa re ni? Awa ni A pin ohun isemi won fun won ninu igbesi aye, A si fi awon ipo gbe apa kan won ga ju apa kan lo nitori ki apa kan won le maa sise fun apa kan, Ike Oluwa re dara ju ohun ti won n kojo lo” (Suurah a-z-Zukruf: 32)

 Olohun ko da won nitori ki awon kan maa foju kere awon miiran, ti awon kan o fi wa maa yepere awon miiran, bi ko se pe nitori a ti le je pe ki awon kan maa saponle awon miiran, ti won o si jo maa gbera won lowo soke, ti won o si jo maa pari ibi ti nnkan ba ku si, ti won o fi ni giga inu isemi. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لاَ يَسْخَرْ قَومٌ مِّن قَوْمٍ عَسَى أَن يَكُونُوا خَيْرًا مِّنْهُمْ وَلاَ نِسَاء مِّن نِّسَاء عَسَى أَن يَكُنَّ خَيْرًا مِّنْهُنَّ وَلاَ تَلْمِزُوا أَنفُسَكُمْ وَلاَ تَنَابَزُوا بِالأَلْقَابِ بِئْسَ الاِسْمُ الْفُسُوقُ بَعْدَ الإِيمَانِ وَمَن لَّمْ يَتُبْ فَأُوْلَئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ" {الحجرات/11}

“Eyin ti e gbagbo ni ododo, awon eniyan kan ko gbodo fi awon eniya n kan se yeye. O le je pe (awon ti won so di oniyeye) dara ju (awon ti n se yeye lo), Awon obinrin kan (ko si gbodo fi) awon obinrin kan (se yeye), O le je pe (awon ti won so di oniyeye) dara ju (awon ti n se yeye lo) Eyin ko gbodo bura yin, Eyin ko si gbodo pe ara yin ni oriki buruku leyin igbagbo ododo, Enikeni ti ko ba ronu piwada, awon wonye ni awon alabosi”. (Suurah al-Hujuroot: 11)

 Idi eyi ni Islaam se kilo fun won nibi gbogbo nnkan ti o le fa ituka fun won, ti awon kan o si korira awon miran, ti eleyi o si wu ote sise sile, ati adiokan buruku, ti yio si je ki jagidijagan be sile laarin awon eniyan ni odidi orile – ede, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَيْلٌ لِّكُلِّ هُمَزَةٍ لُّمَزَةٍ" {الهمزة/1}

“ebge ni fun gbogbo abuniloju – eni abunileyin – eni.” (Suurah al – Humozah: 1)

Islaam ti so wa kuro nibi gbogbo nnkan ti o le ba awujo je, bii adisokan buruku, ati keeta eleyii ti o je ise Esu, ti o si je n ti a tun maa n ri lodo awon elemi buruku, ti won ki i fe daadaa fun elomiran, won o ba maa fi isesi yii da wahala sile, ti ikorira ara won o si maa lekun si I, ti ote o si maa fonka sii ilaarin won, ti awon kan o si pada maa pa awon miiran, ti awon kan kosi ni maa saanu elomiran, tori idi eyi ni ojise Olohun (Ki Ike ati Ola Olohun maa ba a) fi so pe: “E ma maa se keeta ara yin, e maa ma se eru (itumo ni pe e ma yin oja ki o fi le mu iwuri wa de ipo gbigbe owo le e, bee ni ki i se pe e fe ra oja naa), e ma maa korira ara yin, e si ma maa keyin si ara yin, ki abala kan si maa ma ra oja ti eni kan ti ra tele, e je erusin Olohun ni ti jije omo – iya".

 Islaam tun pase ki a maa se gbogbo nnkan ti o le fa isokan, ti yio si fa ibagbepo daadaa, ti yio si fon ife ati alaafia ka saarin wa, Olohun ti Ola re ga so pe:

"لاَّ خَيْرَ فِي كَثِيرٍ مِّن نَّجْوَاهُمْ إِلاَّ مَنْ أَمَرَ بِصَدَقَةٍ أَوْ مَعْرُوفٍ أَوْ إِصْلاَحٍ بَيْنَ النَّاسِ وَمَن يَفْعَلْ ذَلِكَ ابْتَغَاء مَرْضَاتِ اللّهِ فَسَوْفَ نُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا" {النساء/114}

 “Ko si oore ninu opolopo oro ti won ns o ni ikoko ayafi eni ti o fi (oro ikoko) pase sise itore aanu tabi ise rere, tabi atunse laarin awon eniyan, Enikeni ti o ba se iye lati fi wa iyonu Olohun, laipe Awa yoo fun un ni esan ti o tobi” (Suurah a-n-Nisaa: 114)

 

 

IPILE ESIN

            Gege bi o se je pe ipile kan soso ni omoniyan naa lo je pe ipile esin ti Olohun yonusi fun won je okan soso titi di opin – aye, esin kansoso naa si ni Islaam, oun naa ni gbigba lati ju ohunkohun ti Olohun ba fun ni sile fun Olohun ati gbigba lati tele ase Re, ati imaa josin Fun nikan lai morogun mo, Al – Islaam ni esin Baba wa Aadam (ki Alaafia Olohun maa ba a) Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ الدِّينَ عِندَ اللّهِ الإِسْلاَمُ" {آل عمران/19}

“Dajudaju esin ti n be lodo Olohun ni Islaam.” Suurah aali – Imroon: 19)

 Esin kan ni ti o je pe gbogbo ohunkohun ti o ba se yio je ti tori Olohun Oba Olutoju gbogbo eda nikan lo fi se e, ti eda o ni nipin kankan nibe. Gege bi Olohun ti Ola Re ga se so:

"قُلْ إِنَّ صَلاَتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ * لاَ شَرِيكَ لَهُ وَبِذَلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَاْ أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ {الأنعام 162/163}

“So pe: Dajudaju irun mi eran mi (ti mo n pa), Isemi aye mi ati iku mi n je ti Olohun, Oluwa gbogbo eda. * Ko si egbera fun Un. Iye ni Won pa lase fun mi, Emi si ni akoko awon Musulumi (ni asiko temi)” (Suurah al – An’iaam: 162 – 163)

 Gbogbo awon Anabi Olohun patapata (ki ike ati ola Olohun to ga ju maa ba won) leyin Anabi Aadam lo je pe esin won ni Al – Islaam, won si ran won lati pepe sibe, lati le maa yo awon eru Olohun kuro nibi imaa sin eda lo sibi ki won maa sin Oba Adeda, bere latori Anabi Nuha titi de pari won ti i se Muhammad (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلاَّ نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لاَ إِلَهَ إِلاَّ أَنَا فَاعْبُدُونِ" {الأنبياء/25}

“Awa ko ran ojise kan nise siwaju re afi ki A fi imisi ranse si i pe: “Dajudaju ko si Olohun ti Ijosin to si afi Emi (Olohun), Nitori naa, e josin fun Mi”

 (Suurah al – ‘Annbiyaa’: 25)

 Oun ni esin gbogbo awon Anabi Olohun, ko wa fun Anabi kan nikan, ki o ma wa si fun Anabi miira, oun ni esin ti Olohun gbe ofin re kale, ti o si yonu si fun gbogbo eru Re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"شَرَعَ لَكُم مِّنَ الدِّينِ مَا وَصَّى بِهِ نُوحًا وَالَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ وَمَا وَصَّيْنَا بِهِ إِبْرَاهِيمَ وَمُوسَى وَعِيسَى أَنْ أَقِيمُوا الدِّينَ وَلاَ تَتَفَرَّقُوا فِيهِ كَبُرَ عَلَى الْمُشْرِكِينَ مَا تَدْعُوهُمْ إِلَيْهِ اللَّهُ يَجْتَبِي إِلَيْهِ مَن يَشَاء وَيَهْدِي إِلَيْهِ مَن يُنِيبُ" {الشورى/13}

 “(Olohun) se ni ofin fun yin ninu esin (Islaam) oun ti O so asokale re fun (Anabi) Nuuh ati eyi ti O fi ranse si o, ati oun ti A pa lase fun (Anabi) Ibroohiim, muusaa ati ‘Iisaa pe ki e gbe esin naa duro Eyin ko si gbodo pinya si ijo otooto ninu re, ohun ti iwo n pe awon osebo si je inira fun won, Olohun ni O n yan eni ti O ba fe funra re, O si n fi ona mo eni ti o ba n seri si odo Re (ti o ronu piwada)” (Suurah a-s-Suuroo: 13)

 Oun ni ipepe Anabi Ibrohim si awon eniyan (ki Alaafia Olohun maa ba a) eni ti o je Baba awon Anabi Olohun, Olohun ti Ola Re go so pe:

"مَا كَانَ إِبْرَاهِيمُ يَهُودِيًّا وَلاَ نَصْرَانِيًّا وَلَكِن كَانَ حَنِيفًا مُّسْلِمًا وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ" {آل عمران/67}

“(Anabi) Ibroohiim ki i se yehuudi tabi nassara, sugbon o je oluduro deede, musulumi, Ko si si ninu awon osebo. (Suurah aali – ‘Imroon: 67)

 Oun ni asotele Anabi Ibroohim fun omo re lori ohun ti yoo maa se leyin re, oun naa tun ni asotele omo re fun awon omo omo re naa, leyin won, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَوَصَّى بِهَا إِبْرَاهِيمُ بَنِيهِ وَيَعْقُوبُ يَا بَنِيَّ إِنَّ اللّهَ اصْطَفَى لَكُمُ الدِّينَ فَلاَ تَمُوتُنَّ إَلاَّ وَأَنتُم مُّسْلِمُونَ" {البقرة/132}

“(Anabi) Ibroohiim si pa a lase fun awon omo re, (Anabi) Ya’quub naa se bee, (Olukuluku won so pe): “Eyin omo mi, dajudaju Olohun yan esin naa fun yin, Nitori naa, e o gbodo ku ayafi ki e je Musulumi” (Suurah al – Baqoorah: 132)

 Oun naa ni ipepe Musa fun awon eniyan (ki Alaafia Olohun maa ba a) Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَقَالَ مُوسَى يَا قَوْمِ إِن كُنتُمْ آمَنتُم بِاللّهِ فَعَلَيْهِ تَوَكَّلُواْ إِن كُنتُم مُّسْلِمِينَ" {يونس/84}

“(Anabi) Muusaa so pe: “Eyin eniyan mi, ti e ba je eni ti o gba Olohun gbo ni ododo, Oun naa ni ki e gbara le ti e ba je musulumi” (Suurah Yuunus: 84)

 Oun ni esin ti Anabi Hisa (ki Alaafia Olohun maa ba a) ati awon to tele e sin, ti won si pe awon eniyan si, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"فَلَمَّا أَحَسَّ عِيسَى مِنْهُمُ الْكُفْرَ قَالَ مَنْ أَنصَارِي إِلَى اللّهِ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنصَارُ اللّهِ آمَنَّا بِاللّهِ وَاشْهَدْ بِأَنَّا مُسْلِمُونَ" {آل عمران/52}

“Nigba ti (Anabi) Iisa fura si aigbagbo lodo won (pe won fe pa oun), o so pe: “Ta ni oluranlowo mi si odo Olohun?” Awon omoleyin (re) so pe: Awa ni oluranlowo fun (esin) Olohun, A gba Olohun gbo, Ki o si jeri pe dajudaju musulumi ni wa” (Suruah aali – ‘Imroon: 52)

Eyi ni ohun ti Anabi Muhammad (ki ike ati Ola Olohun maa ba) eni ti n se ikeyin awon Anabi Olohun naa kanpa mo pe Islaam ni ipepe si imu Olohun – lokan eyi ti o je ipile esin Gbogbo awon Anabi Olohun ati awon Ojise Olohun, ati pe ohun ti won pare pelu igbedide re (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) na ani awon idajo ofin esin eyi ti won fun awon Anabi Olohun ati Ojise Olohun to gbawaju. O bere pelu awon ofin to pe, ti o kari aye, ti o si dara, O ba gbogbo igba ati aye mu, Sugbon Igbagbo ko yipada ni ti e, Ojise – Olohun (ki ike ati Ola maa ba a) so pe:" Emi ni mo ni eto si Hisa omo Maryam julo laye ati lorun, omo baba kan naa ni awon anobi Olohun ti iya won yato, Iya won lo sotooto, esin kannaa ni esin won.

 Nipa bayi, Islaam ki i se esin aseseda gege bi awon kan se gbagbo bi kii se pe o je ipile eyi ti o dandan ki gbogbo eda abara maa sin lesin, Olohun o si ni gba ki won gba ona miiran sin in. olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَن يَبْتَغِ غَيْرَ الإِسْلاَمِ دِينًا فَلَن يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ" {آل عمران/85}

“eni ti o yan esin miran lesin won o ni gba a lowo re lailai, ni ojo ikeyin ninu awon eni ofo ni yio wa” (Suurah aali – Imroon: 85)

 To ba je pe bi oro se ri niye, a je pe ki oluka iwe yi ya tete pada si ipile esin re, eleyi ti awon baba re wa, ati awon baba baba re ti won mu Olohun lokan, ti won si je eni isiwaju, Ki o gbe jusile nkan adadaale, ti won ba ti mu wo inu re, ti o je pe o ti mu imu Olohun lokan kuro, ti o si fi mimu – orogun – mo Olohun lele, ti o mu ni kuro ninu (Sunnah) ilana ijosin Ojise Olohun lo si bi Adadasile eyi ti o ba lowo awon baba re, ati awon baba baba re ti won de saye keyin, ti o ba maa kose ri pe o kose awon baba to gbawaju, ti won je olumu Olohun lokan, awon ti won n be lori Imu Olohun lokan, mase kose awon baba re tuntun ti won se ayipada esin, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّبِعُوا مَا أَنزَلَ اللَّهُ قَالُوا بَلْ نَتَّبِعُ مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءنَا أَوَلَوْ كَانَ الشَّيْطَانُ يَدْعُوهُمْ إِلَى عَذَابِ السَّعِيرِ" {لقمان/21}

 “Nigba ti won ba si so fun won pe: “E tele ohun ti Olohun sokale.” Won a wi pe: “Rara! A maa tele ohun ti a ba lowo awon baba wa ni.” (Se won yoo tele awon baba won) tohun ti bi esu se n pe won sibi iya ina jonijoni?” (Suurah – Lukmoon: 21)

 Siseri pada sibi ododo lore ju ki a maa ba ibaje lo, koda ki o gba owo re lo, iyi re ati ijoba re. nipa bayi, Idekun gbere lore ju idekun to maa n tan lo, Emi gbagbo pe ti a ba se wadi nipa opolopo itan idile wa, a o ri pe okan lara awon baba nla wa maa je Musulumi, A je pe eyi to dara ju ni ki a tele e, ki o yara (lati tele ododo) ma se maa se royiroyi.

 

 

IBERE IMU OROGUN MO OLOHUN LAARIN AWON ENIYAN:

 Alafo igba ti o wa laarin Adam ati Nuuh (ki Alaafia Olohun maa ba awon mejeeji) je ogorun odun mewa, Awon eniyan igba naa je eni ti n be lori esin kansoso, esin naa si ni (AL – ISLAAM), mimu Olohun lokan ati ai da orogun po mo Olohun, ati imaa sin OUN nikansoso, gege bi Olohun ti Ola Re ga ti se royin re pe:

"كَانَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً فَبَعَثَ اللّهُ النَّبِيِّينَ مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ وَأَنزَلَ مَعَهُمُ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ لِيَحْكُمَ بَيْنَ النَّاسِ فِيمَا اخْتَلَفُواْ فِيهِ وَمَا اخْتَلَفَ فِيهِ إِلاَّ الَّذِينَ أُوتُوهُ مِن بَعْدِ مَا جَاءتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ فَهَدَى اللّهُ الَّذِينَ آمَنُواْ لِمَا اخْتَلَفُواْ فِيهِ مِنَ الْحَقِّ بِإِذْنِهِ وَاللّهُ يَهْدِي مَن يَشَاء إِلَى صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ" {البقرة/213}

“Awon eniyan je ijo kan soso (ninu esin ‘Islaam nipile), Olohun si gbe awon Anabi dide ni oniroo idunnu ati olukilo, O si so Tira kale fun won pelu otito nitori ki O le fi se idajo laaarin awon eniyan nipa ohun ti won yapa enu si, Eni kan ko si yapa enu (si esin Islaam) afi awon ti A fun ni Tira, leyin ti awon eri to yanju de ba won, ni ti ilara laarin ara won, Olohun to awon ti won gbagbo ni ododo sona pelu ase Re nipa ohun ti (awon onilara) yapa enu si ninu ododo (Islaam),Olohun yo maa to eni ti O ba fe si ona taara”. (Suurah al – Baqoorah: 213)

 Abajade adamo lori bi aromodomo Anabi Adam se po, bi iran kan se n lo ni iran kan n de ni pe ki won fi le fonka kaakiri orisirisi aye lori ile fun wiwa Arisiki ati sise iwadi nipa awon aye tio le tuwon lara, nipa bayi abajade fifonka yii ni pe won jinna si ipile to ni alaafia, awon iyapa – enu si be sile laarin won, ati awon agbelero nnkan tuntun, ti adisokan won fi yi pada, ti won si fi sonu kuro lojuona ti o to, ohun ti esu si n fe niyii, Esu ti o mu baba won Adam ati Iya won Hawaa jade kuro ninu Alujannah, ti o si tun n ba adiokan buburu ati keeta re lo lori awon aromodomo Adam (ki Ola Olohun maa ba a) leyin re, ko fi le ri won ju sinu ebo sise ati iyapa ase Olohun, eleyi ti yio gbe won wo ina, gege bi Olohun se royin bayii pe:

"وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلآئِكَةِ اسْجُدُواْ لآدَمَ فَسَجَدُواْ إَلاَّ إِبْلِيسَ قَالَ أَأَسْجُدُ لِمَنْ خَلَقْتَ طِينًا * قَالَ أَرَأَيْتَكَ هَذَا الَّذِي كَرَّمْتَ عَلَيَّ لَئِنْ أَخَّرْتَنِ إِلَى يَوْمِ الْقِيَامَةِ لأَحْتَنِكَنَّ ذُرِّيَّتَهُ إَلاَّ قَلِيلاً * قَالَ اذْهَبْ فَمَن تَبِعَكَ مِنْهُمْ فَإِنَّ جَهَنَّمَ جَزَآؤُكُمْ جَزَاء مَّوْفُورًا" {الإسراء 61/63}

“(Ranti) nigba ti A so fun awon molaaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Aadam, Won si fori kanle ki afi iblis, O wipe: “Se emi yoo fori kanle ki eni ti Iwo fi amo da? * O wi pe: “So fun mi na nipa eyi ti O ponle ju mi lo yii, ki ni o fa a to fi ri bee? Dajudaju ti Iwo ba fi le lo mi lara di Ojo Ajinde, dajudaju maa ko iparun ba awon aromodomo re afi awon die. * (Olohun) so pe: “Maa lo, Enikeni ti o ba tele o ninu won, dajudaju ina Jaanamo ni esan yin, (O si je) esan to kun keke” (Suurah al – Isroo: 61 – 63)

 Akooko jijeyo ebo lori ile ori awon ijo Nuh (ki Ola Olohun maa ba a) lo ti sele. Nigba ti esu se imaa sebo loso fun won ni ti itanje diedie, ki i se loju ese, Nigba ti o se bibere igbetobi fun awon oku inu saree loso fun won, ati kiko ara ro ni be, titi ti O fi ko won sinu ebo – sise, tori idi eyi, lo fi je pe eewo ni ohun ti o je ategun si ebo ninu ofin ijosin esin Islaam, Olohun ti Ola re ga so bayi nipa iroyin won pe:

"قَالَ نُوحٌ رَّبِّ إِنَّهُمْ عَصَوْنِي وَاتَّبَعُوا مَن لَّمْ يَزِدْهُ مَالُهُ وَوَلَدُهُ إِلاَّ خَسَارًا * وَمَكَرُوا مَكْرًا كُبَّارًا * وَقَالُوا لاَ تَذَرُنَّ آلِهَتَكُمْ وَلاَ تَذَرُنَّ وَدًّا وَلاَ سُوَاعًا وَلاَ يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسْرًا" {نوح21/23}

“(Anabi) Nuuh so pe: “Oluwa mi, dajudaju won yapa mi. won si tele eni ti dukia re ati omo re ko se alekun nkankan fun afi ofo. * Won si da ete ni ete to tobi. * Won si wi pe: “E ma se fi awon orisa yin sile, E ma se fi orisa Wadd, Suwaa’u, Yeguuth, Ye’uuq ati Nasr sile” (Suurah Nuuh: 21 – 23)

 Omo Abbas so pe: Oruko awon eniire ijo Anabi Nuh ni wonyi, nigba ti won pa poda tan, esu ranse si awon eniyan won pe ki won gbe oluta tabi ere oosa won, ki won si so won ni awon oruko won ti won je, won si se bee, sugbon won o sin won, titi ti awon eniyan ti o se bee fi ku, ti imo pare, ti awon miiran si bere si maa sin won. (Sahiih Bukhariy)

 Anabi Nuh (ki Ola Olohun maa ba a) lo egberun odun o din Aadota odun to fi n pe awon eniyan re loru ati losan titi to fi lo gbogbo ogbon ipepe to je ti bonkole ati gbangba tan, won se motomoto, won si yapa ase Olohun ti Nuh pa won, Tori idi eyi Anabi Nuh si belohun lewon lori, Olohun si fi omo tuufannu pawon re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قَالَ رَبِّ إِنِّي دَعَوْتُ قَوْمِي لَيْلاً وَنَهَارًا * فَلَمْ يَزِدْهُمْ دُعَائِي إِلاَّ فِرَارًا * وَإِنِّي كُلَّمَا دَعَوْتُهُمْ لِتَغْفِرَ لَهُمْ جَعَلُوا أَصَابِعَهُمْ فِي آذَانِهِمْ وَاسْتَغْشَوْا ثِيَابَهُمْ وَأَصَرُّوا وَاسْتَكْبَرُوا اسْتِكْبَارًا * ثُمَّ إِنِّي دَعَوْتُهُمْ جِهَارًا * ثُمَّ إِنِّي أَعْلَنتُ لَهُمْ وَأَسْرَرْتُ لَهُمْ إِسْرَارًا" {نوح1/9}"

إلى قوله تعالى: "وَقَالَ نُوحٌ رَّبِّ لاَ تَذَرْ عَلَى الأَرْضِ مِنَ الْكَافِرِينَ دَيَّارًا * إِنَّكَ إِن تَذَرْهُمْ يُضِلُّوا عِبَادَكَ وَلاَ يَلِدُوا إِلاَّ فَاجِرًا كَفَّارًا" {نوح26/27}

 “O so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi pe ijo mi ni oru ati ni osan. * Ipe mi ko si se alekun nkan kan fun won ayafi sisa seyin (fun ododo). * Ati pe igbakigba ti mo ba pe won pe ki O le forijin won, won n fi omonika won di eti won, won n yiso won bori, won n taku (si ori ese), won si n jora won loju ni ti igberaga. * Leyin naa, Dajudaju emi tun pe won ni gbangba. * Leyin naa, dajudaju emi tun kede soke fun won, mo si tun pe won pelu ni jeeje” (suarah nuuh 5-9)

De ibi oro (Olohun) ti o so pe:

 " (Anabi) Nuuh so pe: “Oluwa mi, ma se fi eni kan kan sile si ori ile ninu awon alaigbagbo* Dajudaju ti iwo ba fi won sile, won yoo ko isina ba awon eru r, won ko si ni bi omo kan afi eni buruku, alaigbagbo” (Suurah Nuuh: 26 – 27)

Leyin ti Olohun pa awon eniyan Nuuh re, ti Olohun si la oun ati awon olugbagbo ododo to wa pelu e tan, ati awon eda ti o gbe sinu oko oju – omi gege bi Olohun ti o mo julo, ti Ola Re ga se saleye pelu oro re yii:

"حَتَّى إِذَا جَاء أَمْرُنَا وَفَارَ التَّنُّورُ قُلْنَا احْمِلْ فِيهَا مِن كُلٍّ زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ وَأَهْلَكَ إِلاَّ مَن سَبَقَ عَلَيْهِ الْقَوْلُ وَمَنْ آمَنَ وَمَا آمَنَ مَعَهُ إِلاَّ قَلِيلٌ" {هود/40}

“(Bayii ni oro wa) titi di igba ti ase Wa fi de, omi si seyo gburu lati oju – aro (ti won ti n se buredi). A so pe: “Ko sinu oko oju – omi gbogbo nnkan ni orisi meji tako – taboo ati ara ile re – ayafi eni ti oro wa ti ko le lori (fun iparun) – ati enikeni ti o gbagbo ni odododo, Ko si si eni ti o ni igbagbo ododo pelu re afi awon die” (Suurah Huud: 40)

 isemi lori ile tun wa sese bere lotun, pelu awon ti o wa pelu Anabi Nuuh ti won je olugbagbo ododo, nigba ti asiko pe ti awon ye ti ku, awon eniyan miiran wa leyin won, ti esu si se loso fun won sise ere awon baba won ti won la kuro nibi omi Tuufan, ki awon o fi le maa ranti won titi ti oro naa fi dagbasoke de ipo imaa sin won, tori idi eyi ni Olohun fi ran Anabi Huud (ki Ola Olohun maa baa ) ko fi le dawon pada sibi esin to ni alaafia, sugbon won ko lati tele ase Olohun, won yapa ase re, tori idi eyi, Olohun si fi ategun iji gbigbona pawon run. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَاذْكُرْ أَخَا عَادٍ إِذْ أَنذَرَ قَوْمَهُ بِالأَحْقَافِ وَقَدْ خَلَتْ النُّذُرُ مِن بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ أَلاَّ تَعْبُدُوا إِلاَّ اللَّهَ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ * قَالُوا أَجِئْتَنَا لِتَأْفِكَنَا عَنْ آلِهَتِنَا فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ * قَالَ إِنَّمَا الْعِلْمُ عِندَ اللَّهِ وَأُبَلِّغُكُم مَّا أُرْسِلْتُ بِهِ وَلَكِنِّي أَرَاكُمْ قَوْمًا تَجْهَلُونَ * فَلَمَّا رَأَوْهُ عَارِضًا مُّسْتَقْبِلَ أَوْدِيَتِهِمْ قَالُوا هَذَا عَارِضٌ مُّمْطِرُنَا بَلْ هُوَ مَا اسْتَعْجَلْتُم بِهِ رِيحٌ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمٌ * تُدَمِّرُ كُلَّ شَيْءٍ بِأَمْرِ رَبِّهَا فَأَصْبَحُوا لاَ يُرَى إِلاَّ مَسَاكِنُهُمْ كَذَلِكَ نَجْزِي الْقَوْمَ الْمُجْرِمِينَ" {الأحقاف21/25}

“(Ranit) arakunrin (ijo) ‘Aad, nigba ti o se ikilo fun awon eniyan re ti n gbe ninu yanriin ti ategun kojo si oke. Awon olukilo si ti re koja lo siwaju re ati leyin re, (O si so pe) “Eyin ko gbodo josin fun kinni kan ayafi Olohun, Dajudaju emi n beru iya ojo nla lori yin” * Won wi pe: “Se iwo wa ba wa lati le se wa lori kuro nibi awon orisa wa ni? mu ohun ti o n se ileri re fun wa wa ti iwo ba wa ninu awon olododo * O so pe: “Imo (nipa re) wa ni odo Olohun nikan soso, Emi yo si je ise ti Won fi ran mi de opin fun yin, sugbon emi n ri eyin ni ijo alaimokan” * Nigbati won ri (iya naa0 ni esujo regede, ti n wo bo sinu awon koto ilu won, won wi pe: “Eyi ni esujo regede, ti o maa rojo fun wa, Ko ri bee, ohun ti e nwa pelu ikanju ni, ategun ti iya eleta – elero wa ninu re ni, * O n pa gbogbo nnkan re pelu ase Oluwa re. nigba naa, won di eni ti won ko n mo afi awon ibugbe won, Baye ni A se n san ijo elese ni esan” (Suurah al – Ahqoof: 21 – 25)

 Leyin naa, awon iran Samuuda naa tun wa leyin awon iran Aadi, won si n sin awon ere orisa, tori idi eyi, Olohun ran Anabi Solih (Ki Ola Olohun maa ba a) si won, ko fi dawon pada sibi sisin Olohun, sugbon won pe e niro, tori idi eyi, Olohun pa won re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهْلِكُوا بِالطَّاغِيَةِ" {الحاقة/5}

“Ni ti ijo Thamuud, A fi igbe to tayo enu aala pa won re” (Suurah al – haaqooh: 5)

 Awon eniyan Anabi Ibarhiim, baba awon Anabi Olohun, (ki Ola Olohun maa ba a) naa sin awon irawo, ati awon ere orisa, Anabi Ibrahim si ni ki won sora, O si ko fun won nipa re, sugbon won ko da a lohun, Olohun si tori re pa won re, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَقَدْ آتَيْنَا إِبْرَاهِيمَ رُشْدَهُ مِن قَبْلُ وَكُنَّا بِه عَالِمِينَ * إِذْ قَالَ لإِبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا هَذِهِ التَّمَاثِيلُ الَّتِي أَنتُمْ لَهَا عَاكِفُونَ * قَالُوا وَجَدْنَا آبَاءنَا لَهَا عَابِدِينَ * قَالَ لَقَدْ كُنتُمْ أَنتُمْ وَآبَاؤُكُمْ فِي ضَلاَلٍ مُّبِينٍ {الأنبياء51/54}

“Dajudaju A ti fun (Anabi) ibroohim ni imona tire siwaju (ki o to dagba), A wa si n je Onimo nipa re. * (Ranti) nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: “ki ni awon ere wonyi ti en josin fun? * Won wi pe: “A baa won baba wa ti won n josin fun won ni * O so pe: “Dajudaju eyin ati awon baba yin ti wa ninu isina ponnbele”

(Suurah al – Anbiyya: 51 – 54)

 Leyin naa ni awon omo Isreli de, Olohun si ran Anabi Musa (ki Ola Olohun maa ba a) si won, won ba mu ogedegbe malu, won ba n sin in leyin Olohun, iye si bi ibere ebo laarin won. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَاتَّخَذَ قَوْمُ مُوسَى مِن بَعْدِهِ مِنْ حُلِيِّهِمْ عِجْلاً جَسَدًا لَّهُ خُوَارٌ أَلَمْ يَرَوْاْ أَنَّهُ لاَ يُكَلِّمُهُمْ وَلاَ يَهْدِيهِمْ سَبِيلاً اتَّخَذُوهُ وَكَانُواْ ظَالِمِينَ" {الأعراف/148}

“Awon eniyan (Anabi) Muusaa, leyin re (nigba ti o fi lo ba Olohun soro), won mu ninu oso won (lati fi se) ere omo maalu oborogidi, o si n dun (bii maalu), Se won ko ri i pe dajudaju ko le ba won soro ni, ko si le fi ona mo won? Won si so o di akunlebo, Won si je alabosi” (Suurah Al – a’raaf: 148)

 Leyin naa ni won tun josin fun Uzaeru lowo igbeyin igba won, tori idi eyi ni Olohun fi gbe Anabi Hisa (ki Ola Olohun maa ba a) ko fi le dawon pada sibi Imu Olohun lokan, ati imaa sin Olohun lOun nikansoso, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُم مُّصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِن بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ فَلَمَّا جَاءهُم بِالْبَيِّنَاتِ قَالُوا هَذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ" {الصف/6}

“(Ranti) nigba ti iisaa omo Moryam so pe: “Eyin omo Isroo’ill, dajudaju emi ni Ojise Olohun si yin 9gege bi) olufi idi – ododo – mule nipa ohun ti o ti siwaju mi ninu a-t-Taorah, ti mo si je oniroo – idunni nipa Ojise kan ti n bo ni eyin mi, oruko re ni “Ahmod” Nigba ti o si de ba won pelu eri to yanju, won wi pe: “Idan ponnbele ni eyi”. (Suurah a-s-Soff: 6)

 Koda, oro yi tun dagbasoke laarin won de ibi wi pe won fi n sin Anabi Hisa (ki Ola Olohun maa ba a) dipo imaa sin Olohun, won so pe omo Olohun ni, won tun so pe iketa Olohun meta ni, Bee Olohun ga tayo gbogbo nkan ti won n so wonyi, ni giga ti O tobi pupo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لاَ تَغْلُواْ فِي دِينِكُمْ وَلاَ تَقُولُواْ عَلَى اللّهِ إِلاَّ الْحَقِّ إِنَّمَا الْمَسِيحُ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ رَسُولُ اللّهِ وَكَلِمَتُهُ أَلْقَاهَا إِلَى مَرْيَمَ وَرُوحٌ مِّنْهُ فَآمِنُواْ بِاللّهِ وَرُسُلِهِ وَلاَ تَقُولُواْ ثَلاَثَةٌ انتَهُواْ خَيْرًا لَّكُمْ إِنَّمَا اللّهُ إِلَهٌ وَاحِدٌ سُبْحَانَهُ أَن يَكُونَ لَهُ وَلَدٌ لَّهُ مَا فِي السَّمَاوَات وَمَا فِي الأَرْضِ وَكَفَى بِاللّهِ وَكِيلاً" {النساء/171}

 “Eyin ara-oni tira! e ma se tayo enu – aala ninu esin yin, e si ma se so n kan nipa Olohun afi ododo, Mosiih ‘Iisaa omo Moryam ko je kini kan tayo Ojise Olohun ati 9pe)o je oro re (kun fayakun) ti O so ranse si moryam (ni O fi se eda re), ati emi kan ( ti O seda) lati odo Re (ni Mosiih ‘Iisaa omo Moryam), Notir naa, e ni igbagbo ododo ninu Olohun ati awon Ojise Re. e yee so meta (loka) mo, Ki e jawo nibe lo je oore fun yin, Olohun nikan ni Olohun ti ijosin to si, Okan soso, O mo tayo ki O ni omo, Ti Re ni ohunkohun ti n be ninu awon sanmo ati ile, Olohun si to ni Alamojuto. (Suurah a-n-Nisaa: 171)

 Ogorun mefa odun lo si n be laarin igba Anabi Hisa (ki Ola Olohun maa ba a) ati igbedide Anabi Muhammad (ki Ike ati Ola Olohun maa ba a) ebo sise ti gbile kaakiri Gbogbo ori – ile lasiko ye, de ibi wi pe osunmo ki awon olu sin Olohun lododo pasofo lori ile – ayafi awon kan ninu awon eni ti won fun ni tira, to n sin Olohun lori ilana ijosin Anabi Ibrohiim Al – Khaliil (ki Ola Olohun maa ba a) Awon naa ni – awon to n tele Aryoos laarin re si ni esu tun se imaa sin nnkan miiran leyin Olohun loso fun awon eniyan, o se imaa sin inan loso fun awon kan, o si se omi, okuta, igi, malu tabi imaa sin esu gan – an fun ra ra loso fawon miran, gbogbo enikookan si n sinn Ohun ti o fe ni ibamu si ohun ti laakaye ati ironu re ba se loso fun un. Eleyii lo si so omoniyan di ki o maa tele eda egbe re, ti won si fi dipe won n sin awon eda bii ti won, ti o se pe won je eda ti o kagara lori sise anfaani fun emi ara ti won gan – an, kato wa so sise anfaani fun elomiran, Ododo ni oro Olohun ti o so pe:

"وَالَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِهِ مَا يَمْلِكُونَ مِن قِطْمِيرٍ * إِن تَدْعُوهُمْ لاَ يَسْمَعُوا دُعَاءكُمْ وَلَوْ سَمِعُوا مَا اسْتَجَابُوا لَكُمْ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ يَكْفُرُونَ بِشِرْكِكُمْ وَلاَ يُنَبِّئُكَ مِثْلُ خَبِيرٍ" {فاطر13/14}

“Awon ti e si n ke pe leyin Re, won ko ni ikapa kan lori epo koro inu dabidun, * Ti eyin ba pe won, won ko le gbo ipe yin, Ti o ba si je pe won gbo, won ko le da yin lohu. Ati pe ni Ojo Ajinde, won yoo tako bi e se fi won se egbera fun Olohun, Ko si si eni ti o le fun o ni iro kan (nipa eda to le tayo) iru (iro ti) Olumo – ikoko (fun o nipa won). (Suurah Faatir: 13 – 14)

 Alfa Agba AL – kaero wanniy. So aworan bi igba Okunkun yen se ri ninu oro bayi pe: "Anabi Muhammad (ki Ike ati Ola ma ba a) jade ni asiko ti awon eniyan wa bukata si eni ti yoo maa fi ona mo won lo si oju ona ti o to, ti o si maa to won sona lo sibi esin ti o duro deede, tori pe awon larubawa wa lori esin iborisa, ati imaa pa awon omobinrin, ati imaa ni adisokan pe Olohun pe meji, Olohun kan lo ni Oore, Olohun kan lo ni Aburu, Olohun Oloore lo ni imole, Olohun Alaburu lo ni okunkun, bakan naa won a maa ba iya won lo po, won a si maa ba omobinrin won lo po, awon ijo Tatar naa sin be lori siso ile dahoro, imaa fiya nla je awon eru, imaa sin malu, imaa forikanle fun igi ati okuta, awon Yahuudi inu won naa tun wa lori iyanjija ati esin imaa se afijo Olohun Adeda pelu eda, ati imaa se igbelaruge iro pipa ati adapa iro, ti awon Nasooroh inu won si n be lori esin meta lokan, ati esin Alagbelebu, ati awon esin aworan awon eni mimo lokunrin lobinrin, bayi gele ni gbogbo eya larubawa ri nibi wiwa lori anu, ati igunri kuro nibi ododo, ati kiko airoju pelu iro, ko leto ki o ma je pe Olohun Oba ti O ni gbogbo nnkan ma ran enikan nise, ti yoo le je ike fun gbogbo aye ni asiko yen, eni kan o si foju han pe o dara fun ise nla yii, ti yoo si le mo ile ti o duro daada yi yato si Muhammad Omo Abdullahi (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) ni pa bayii Anabi (ki Ike ati Ola Olohun maa ba a) ba mu gbogbo nnkan to mu ki awon eniyan gunri sibi ibaje kuro, ti o si mu awon oro ibaje naa kuro, ti O si tan Oorun imu Olohun lokan, O si tun tan osupa afomo esin fun Olohun nikan, ti Okunkun ebo si di ohun ti o ye kuro, ti mimu Olohun ni meji meji naa si ye kur, ti igbagbo meta lokan nipa imaa fi Olohun we eda naa si ye kuro pelu okunfa ise Anabi (ki eyi to lola ju ninu Ola ati kiki ti o pe ju ninu kiki maa ba a), Laarin iboji ipo yii, ati awon ise ti won fi le le yii, ni won ti gbe Annabi Muhammad (ki Ike ati Ola maa ba a) dide nigba ti o pe omo ogoji odun ninu ojo ori re, ti Olohun ti Ola Re ga si sa a lesa gegebi Olohun ti sa awon Anabi Olohun to gbawaju re. bii Nuh, Ibrohim, Musa ati Hisa, ti Olohun si so ofin kan to dara pupo kale, ti o je ofin to ba igba ati aye mu ti o si ko awon ofin esin ti won o jeki gbogbo omoniyan maa semi ninu ifkonable ati itura sinu, ati ninu igbaaye ike ati isemi Alaponle fun gbogbo eniyan, ninu awon nnkan ti o toka si iyen nip e: ofin kan ninu ofin esin ti to fun agboye ohun ti mo so. Ojise Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) so pe: "Dajudaju awon eje yin, awon dukia yin, awon omoluabi yin je eewo laarin yin, gege bi a se se awon nkan leewo fun yi lojo oni yii (Mutaffak Alaei).

 Ipepe re naa da gege bi ipepe awon omo – iya re ti won je awon Anabi Olohun to waye siwaju re nibi pipe lo sibi igbagbo si Olohun okansoso ati aisi imu orogun mo Olohun, ipepe si bi daadaa ni gbogbo ona ati wiwa iso kuro nibi imu orogun mo Olohun, ipepe sibi gbgbo ohun to dara ati wiwa isora kuro nibi mimu orogun mo Olohun, Ipepe sibi gbogbo ohun to dara, ati wiwa isora fun Gbogbo aburu, ti dide re si je ike fun gbogbo aye, ti o si je ike fun gbogbo eda lapapo, lati yo won jade kuro nibi anu ati aimokan ti won ti ntesebese lori e, Olohun ti Ola re ga so pe:

"لَقَدْ مَنَّ اللّهُ عَلَى الْمُؤمِنِينَ إِذْ بَعَثَ فِيهِمْ رَسُولاً مِّنْ أَنفُسِهِمْ يَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِهِ وَيُزَكِّيهِمْ وَيُعَلِّمُهُمُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَإِن كَانُواْ مِن قَبْلُ لَفِي ضَلالٍ مُّبِينٍ" {آل عمران/164}

 “Olohun ti se oore fun awon onigbagbo ododo, nigba ti O gbe Ojise kan dide si won laarin ara won, (Ojise naa) n ke awon aayah Re fun won, O n fo won mo, O si n ko won ni tira (al – Qur’aan) ati oye esin sunnah), bi o tile je pe teletele won wa ninu isina ponnbele” (Suurah aali – Imroon: 164)

 Pelu gbigbe dide Ojise – Olohun si ni esin omoniyan fi pe perepere, ti idekun ibe si fi pari patapata, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الإِسْلاَمَ دِينًا " {المائدة/3}

“Lonii ni Mo pa ri esin yin fun yin, Mo si se asepe idera mi fun yin, Mo si yonu si Islaam ni esin fun yin”. (Suurah al – Moo’idah: 3)

 Eleyii mu nki ibere kan seyo ninu opolo, ohun naa ni pe? nje gbogbo eto agbekale, ati ofin atowoda omoniya ti won n pe omoniyan si be ni aye ode oni, ni osan ati loru n je ohun ti o koriire ba won ni? Nje O mu opin ba osi won bi? Nje o mu awon ona isemi tororun bawon bi? Nje O ko aponle ba jije omoniyan won bi? Nje o fun won ni ojulowo ominira eyi ti O le so anponle ara omoniyan fun un bi? Abi o je ominira to mu idaamu lowo ti o fun won ni ominira ibaje, ati atako fun iwa rere, ati fun Gbogbo ofin – esin?

 Ju awon ibeere wonyi si ara re, ki o si wo Agbaye ayika re, O o ripe anfaani awon eto wonyi wa fun awon orile – ede kan, ko si fun awon orile – ede miira, o wa fun awon eniyan kan kosi fun awon eniyan miran, o wa fun awon akojo eniyan kan pato tiwon fe mu awon miiran leru ninu eda bara, ti won fe ko ebi ba opolopo aye lori ile, Idi agbekale ofin won duro lori eto aye lasan ni! imunisin awon ilu kan ati imunileru lo je fun omoniyan, Idi agbekale to duro lori eto aye lasan ni, awon ogun ati rogbodiyan ti o se pe ohun to sokunfa re ni eto aye lasan, ohun ti awon ofin agbelero ati awon eto agbaye gbe wa niyi, Nipa bayii, e pada si ipile yi, e o jere, e o si soriire laye ati lorun.

 

 

WIWA BUKATA OMONIYAN SI RIRAN AWON OJISE NISE

            Omoniyan ti ko ba ni esin ati ofin – esin da bii awon eranko ti ko ni afojusun kakan ayafi atuse ara re nikan, laiwo awon ona wo lo dara lati ri atunse ara re yii, ofin atowoda yio maa dari eni lona abosi, nitori pe nibe ni alagbara ti n je ole, ti o si n mu aanu kuro lokan, Eleyii ti o se pe esin ati ofin esin si n je Ike fun gbogbo eda abara lapapo, o si leto ki a pepe fun amulo re, tori pe gbogbo eto ati isemi alapnle lo ko sinu, ni asiko iroro re, ati ni igba aini re, ni igba ti o ni Alaafia, ni igba ti o n saisan, ni gba ti o ni agbara, ni igba ti o je ole. Ki o fi le mo ohun ti a n so daada, teti gbo abala kan ninu awon abala ofin – esin ti won so kale fun Muhammad Ojise – Olohun (ki Ike ati Ola maa ba a) eleyii ti o ko awon eto omoniyan sinu, yio mo wa baa koda ki o mo daamu fun a tile ri awon eto naa lopin igba ti omoniyan ba ti n tele e. ojise Olohun (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) so pe: “Gbogbo yin la o si bi leere nipa eran ti o daje, Adaranje ni Imam je, won o si bi i nipa eran re ti o da je, okunrin (ti o je oko) naa je Adaranje fun awon ara 0 ile re, won si maa bi i nipa awon eran re ti o da je, Adaranje ni obinrin (ti o je iyawo) naa je ninu ile oko re, won o si bi oun naa nipa eran re ti o daje, Adaranje ni omo – odo naa je nipa dukia oga re, won o si bi nipa eran re ti o daje, eni ti o gba Hadith yi wa) so pe: Mo lero pe, o tun so: Adaranje ni eniyan je nipa dukia baba re, won o si bi i nipa eran re ti o daje, Gbogbo yin ni Adaranje, gbogbo yin si ni a O bi nipa eran ti o daje (Muttafak Alaei)

 Idi niyi, ti Olohun ti o gbon – ngbon ti Ola Re ga fi se riran awon Ojise – Olohun nise ni onan kan ninu awon onan ti o se pe Olohun fi ke omoniyan, ti o si tun je ike ninu awon ike Olohun ti o fi gbola fun won, nipa wi pe, ko gbe won ju sile lasan, ti yio fi maa wa dipe awon ife – inu ati aba dida o maa wa fa won, bakan naa, ko fi won da laakaye won, o ni enu ala ibi ti o lagbara mo, o si tun le, o kagara nipa fifi ona mo won laisi ofin esin, ohun ti Olohun fun eniyan ninu awon ategun dida nnkan mo ati imo, bii oore igboran, Iriran, ati Laakaye koni agbaran lori imona won, ati itosona won sibi ona ti o maa mu won de ogongo ibi ti won ti tori re da won, kosi tun le lagbara lati fi awon ofin esin ati ofin eto aye le le fun won, eleyi ti O le mu ki isemi won lo leto leto, ti o si le fi idi deede sise mule laarin won, ti yio si mu ki idagbasoke wa fun won, ti yio si ba won so ije – omoniyan won, ti enikan o fi ni maa dola lori elomirina ayaf i pelu iberu – Olohun ati ise’re, ti yio si je ofin kan ti ko ni maa teriba fun ife – inu, ti o je kaari aye, ti yio si je eyi ti o dara fun gbogbo igba ati gbogbo aye, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا بَنِي آدَمَ إِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ رُسُلٌ مِّنكُمْ يَقُصُّونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِي فَمَنِ اتَّقَى وَأَصْلَحَ فَلاَ خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ * وَالَّذِينَ كَذَّبُواْ بِآيَاتِنَا وَاسْتَكْبَرُواْ عَنْهَا أُوْلَئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ" {الأعراف35/36}

“Eyin omo (Anabi) Aadam, nigba ti awon Ojise ninu yin ba wa ba yin, ti won yoo maa ka awon aayah mi fun yin, enikeni ti o ba paya (Mi), ti o si se atunse, ko nii si iberu kan fun won, won ko si nii banuje * Awon ti won ba si pe awon aayah Wa niro, ti won si se igberaga si i, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re” (Suurah al-a’raaf: 35 – 36)

 Adamo omoniyan, ati eto ti Olohun da a le lori ko to fun un lati lagbara ise nla yii, eleyi kosi je aleebu fun un, bi ko se pe oro adamo lo je, o si n tokasi wiwa bukata re sodo Adedaa kan yoo gbe rin lo sibi Ojuona ati ilana esin to baamu, ti O si le satunse ise re, nipa bayii, awon laakaye le, ko lagbara ki o maa seto isesi eni ti o nii, bawo lo se wa le lagbara ki o maa seto isesi gbogbo omoniyan lapapo pelu ikagara re ati ogbon kekere to wa fun un, ati iwo o jumi emi ju o to wa fun un, ati awon iyapa – enu re, nibi yiyo ofin kan kuro, fun omiran, nnkan to je daadaa lodo awon kan le maa je daadaa lodo awon miran, nitoripe kosi ikapa fun lati mo ohun ti n lo ni agbaye miiran ti a o foye mo, ati a i le nikapa mimo ohun to le sele lojo iwaju, nnkan to n je gbigba wole loni le je aigba wole lola. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يُرِيدُ اللّهُ أَن يُخَفِّفَ عَنكُمْ وَخُلِقَ الإِنسَانُ ضَعِيفًا" {النساء/28}

“Olohun fe se irorun fun yin; A si seda eniyan ni ole” (Suurah a-n-Nisaa: 28)

 Bakannaa ni adamo re ti Olohun da a le lori nipa kikanju sisele nkan ati gbigbon wiriwiri Omoniyan fun nnkan, ati a i le duro re lori isesi kan, o maa n fe nnkan, o si maa n korira nnkan, a maa mu nnkan wa, a si maa ko nnkan, a maa n se iranlowo fun nnkan, a si maa se atako fun nnkan ati beebee lo, Gbogbo awon nnkan wonyi O ko abuku ba omoniyan, oun ni o fa ti ko fi le se eto isemi omoniyan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَيَدْعُ الإِنسَانُ بِالشَّرِّ دُعَاءهُ بِالْخَيْرِ وَكَانَ الإِنسَانُ عَجُولاً" {الإسراء/11}

“Eniyan si n toro aburu bi o se n toro ohun rere; eniyan si je onikanju”

 (Suurah al – Isroo: 11)

Bee naaa ni Lilo bibo opolo, ati aiduro re si ojukan, won se admon opolo omoniyan ni opo igba lori inife si gbigba nnkan ju fifun eniyan ni nnkan lo, O si tun maa n fe Adanikanje ju pe ki o gbola fun ki elomiran koko ri oore siwaju re, o si maa n fe didiwo mo oore ju ninan oore lo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُل لَّوْ أَنتُمْ تَمْلِكُونَ خَزَآئِنَ رَحْمَةِ رَبِّي إِذًا لاَّمْسَكْتُمْ خَشْيَةَ الإِنفَاقِ وَكَانَ الإنسَانُ قَتُورًا" {الإسراء/100}

“So pe: “Ti o ba je pe eyin le ni ikapa lori awon apepe oro ike Oluwa mi, nigba naa nse ni e ma di i mowo ni ti iberu osi, Eniyan si je ahun” (Suurah al’Isroo: 100)

Lafikun, won da laakaye lori igbagbe ati aini amotan gbogbo nkan, nnkan ti o je otito loni, nnkan naa le je asise lola ati bee bee lo.

 Awon iwoye kan si tun n be nibi bo se je pe opolo omoniyan maa se idajo kan lanan pe nnkan kan ni alaafia ti yio si di pe opolo omoniyan o tun pada pe nnkan naa niro loni, gege bi o se je pe opolo omoniyan ki i se ohun ti won so kuro nibi asise, nipa bayi o maa n mu awon abajade wa lori mimo oro pa sibi agbekale isesi ti o wa fun nnkan, tabi ni ibamu si ipo to han sita, Wo ayyika re oo ri I pe opolopo awon eto awon orile – ede eyi ti awon eni esa ninu awon Alarojinle eda gbe kale ti bere si ni maa yipada fun awon idi isele kan ti awon orile – ede yi n la koja, nipa bayii, yio ba di ohun ti ayipada o ba, ni ibami si agbekale isesi, awon laakaye won o ba so di ofin, won o ba maa lo o, yio ba dip e aini fidimule ati aini le satunse lo ni gbogbo igba ati aye, yio ba di dandan ko sele, ko da bii ofin Olohun Oba Olutoju eda, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ الإِنسَانَ خُلِقَ هَلُوعًا * إِذَا مَسَّهُ الشَّرُّ جَزُوعًا" {المعارج19/20}

“Dajudaju eniyan, A seda re (O si je) alailokan, okanjua * Nigba ti aburu ba fowo ba a, o maa kanra gogo” (Suurah al – Mo’aarij: 19 – 20)

 Leyin naa, e je ki a tun wo awon nkan ti opolo gbe kale fun awujo omoniyan ninu awon irinse ija, ipara eni, iso nnkan di ofo, lati ara nnkan ti won hun funra won, ninu awon irinse ti orile – ede ati awon erusin be fi n semi, ti won tun fi n se iyanran bi agbara won se to lori eto aye, Awon oloye so pe: Se ki i se pe eyi wa ninu awon abajade ohun ti o pamo sibi isemi won, ati aini igbagbo si nnkan ti o pamo ninu bi o se je pe igbende leyin iku nbe, akojo leyin igbende, isiro ise n be, ti emi base daadaa laye, yio gbesan daada, ti o ba si saida, yo gbesan aida, nigba ti o je pe ti won ba gba awon nnkan to pamo wonyi gbo, won o ni se nnkan kan, ayafi ki o je ohun ti o maa lore fun won ati fun gbogbo omoniyan, ti won yoo si jinna si gbogbo eniyan lati se won ni aida, Olohun ti Ola Re ga so pe:

فَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًا يَرَهُ * وَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُ {الزلزلة7/8}

“Nitori naa, eni ti o ba se ise rere ni odiwon omo – ina – igun, o maa ri i * Eni ti o ba si se ise aburu ni odiwon omo – ina – igun, o maa ri” (Suurah a-z- Zalzalah: 7-8)

 Bakan naa, awon opolo omoniyan labe aini igbagbo si awon nnkan to pamo, ko ni lagbara ati mu nkan ti won n sin wa, ayafi ki o je awon ohun ti won mo lori awon ibugbe eniyan, gege bi awon okuta ati awon igi, tabi awon ohun ti won n sin ti yi o fa ki onje won ati nkan mimu won le jinna, gege bi ipese ina fun a ti se ounje, tabi awon nnkan ti won n sin eleyi ti omoniyan o maa je gege bii awon malu, tabi awon ohun ti won n sin ti won n pa, gege bii awon eku, tabi awon ohun ti won n sin ti won si fi rinle pe oun ni ipile aburu gege bi awon esu ati bee bee lo.

 Tori idie eyi, riran awon ojise nise wa lara awon ohun ti dida won nilo, ki won o fi le salaye fun won awon ofin ti o maa so gbogbo won kuro nibi asise ti yio si salaye awon idajo to ba oro mu.

 Gegebi a ti so pe eda abara pelu laakye ti won fun won, ati imo ti won fun won, gbogbo nnkan ti won le mo koju owo imo nipa awon nkan afoju ri, sugbon nnkan to ba ti bo si eyin eyi ninu awon imo ohun to pamo, won ko le da mo ayafi lati ona odo awon Ojise, lapere, itan nipa awon ijo to ti kuro laye tipetipe siwaju wa, a ko le mo on, a ko le damo ayafi lati ibi ohun ti awon akotan ko sile, ti kii ba se akosile won, bi gbogbo onimimo ba lo opolo won lati le da mo, won o le mo on, bakan naa awon ojise gan – an naa o le mo, eyi je aponle ti Olohun se fun won, bi O se ran won nise, ni awon igba ti awon eniyan ba jinna si oju ona ti o to, ni Olohun maa n gbe awon Ojise dide fun won, ti awon ojie yii o si maa dawon pada soju ona, ti won yoo si maa salaye awon ofin esin ti a le seto oro won gun rege, ni okookan won ati lapapo, oju ona ti won yoo si maa rin ti won yoo fi de ibi eto ti o gun rege, ati pe ki awijare le wa nibi riran won si awon eniyan, gege bi Olohun ti o mo julo, ti Ola Re ga se so pe:

"رُّسُلاً مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلاَّ يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى اللّهِ حُجَّةٌ بَعْدَ الرُّسُلِ وَكَانَ اللّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا" {النساء/165}

“(A se won ni) Ojise, oniroo idunnu ati olukilo nitori ki awijare ma se wa fun awon eniyan lodo Olohun leyin ti) awon Ojise (ti jise), Olohun si n je Alagbara, Ologbon” (Suurah a-n-Nisaa: 165)

 Imisi ti Olohun so kale fun awon Ojise lo maa n je ise omoniyan maa seku lori daadaa, ohun ni imole ti won o maa ri ojo iwaju latara re, ti won yoo si fi maa ri imole ninu awon okunkun aimokan, ohun si ni oju ona ti won a fi yo kuro ninu anu, oriire won tabi ori buruku won yio si maa so mo gbigba mu ti won ba gba a mu, tabi kiko ti won ba ko lati gba mu, kosi oju ona kan ti won fi le de odo Eledaa won ayafi lati ibi ise imisi, sugbon ona miiran yato si eyi, iparun ni, Anu si tun ni pelu, gegebi Olohun se royin pelu oro re bayi pe:

"قُلْ أَنَدْعُو مِن دُونِ اللّهِ مَا لاَ يَنفَعُنَا وَلاَ يَضُرُّنَا وَنُرَدُّ عَلَى أَعْقَابِنَا بَعْدَ إِذْ هَدَانَا اللّهُ كَالَّذِي اسْتَهْوَتْهُ الشَّيَاطِينُ فِي الأَرْضِ حَيْرَانَ لَهُ أَصْحَابٌ يَدْعُونَهُ إِلَى الْهُدَى ائْتِنَا قُلْ إِنَّ هُدَى اللّهِ هُوَ الْهُدَىَ وَأُمِرْنَا لِنُسْلِمَ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ" {الأنعام/71}

“So pe: “Se awa yoo maa ke pe leyin Olohun, ohun ti ko le se wa ni anfani, ti ko si le ko inira ba wa; (se) ki won tun da wa pada si ese – aaro wa leyin igba ti Olohun ti fi ona mo wa (ki a le da) bi eni ti Esu si lona lori ile, ti idaamu de ba? O (si) ni awon ore kan ti won n pe e sibi imona (pe), maa bo ni odo wa, “So pe: “Imona ti Olohun (Islaam), ohun ni imona, Won si pa wa lase pe ki a gba esin ‘Islaam nitori ti Oluwa gbogbo eda”. (Suurah al-Ani’aam: 71)

 Leyin naa sise esa wa fun amoniyan nipa gbigba ohun ti Olohun so kale fun awon Ojise re tabi kiko, Fun idi eyi eni ti o ba gba, o ti soriire, eni ti o ba si ko o ti sori bu, gege bi Olohun ti mimo je ti E se so:

"وَلَوْ شَاء رَبُّكَ لآمَنَ مَن فِي الأَرْضِ كُلُّهُمْ جَمِيعًا أَفَأَنتَ تُكْرِهُ النَّاسَ حَتَّى يَكُونُواْ مُؤْمِنِينَ" {يونس/99}

“ti Oluwa re ba fe bee ni, awon ti n be lori ile iba gbagbo, gbogbo won patapata, Nitori naa, se iwo ni o maa je won nipa ni titi won yoo fi di onigbagbo ododod?”

(Suurah Yuunus: 99)

Ododo loro Oba Adeeda, mimo fun Olohun ti Ola Re ga ti o salaye pe imisi ti won sokale fun awon Ojise Olohun wa gege bi ipo emi si ara ni, gege bi o se je pe isemi ara kole si ayafi pelu emi, bee naa ni isemi awon okan omonyan ri, irinle okan won, ati ifayabale re kole si ayafi latari imisi imona Olohun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَكَذَلِكَ أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ رُوحًا مِّنْ أَمْرِنَا مَا كُنتَ تَدْرِي مَا الْكِتَابُ وَلاَ الإِيمَانُ وَلَكِن جَعَلْنَاهُ نُورًا نَّهْدِي بِهِ مَنْ نَّشَاء مِنْ عِبَادِنَا وَإِنَّكَ لَتَهْدِي إِلَى صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ" {الشورى/52}

“Bayen si ni A se fi imisi ranse si o ninu ase Wa, Iwo ko mo ki ni Tira tabi ki ni igbagbo (siwaju imisi naa), sugbon A se e ni imole kan ti A fi n se itosona fun eni ti A ba fe ninu awon erusin Wa, Dajudaju iwo n to (awon eniyan) si ona taara (ninu Islaam)” (Suurah a-s-Suuroo: 52)

 

 

IJE EDA ABARA TI AWON ANOBI OLOHUN ATI AWON OJISE JE (ki alaafia Olohun maa ba won)

            Gbogbo awon ti Olohun maa n ran nise, ti won maa n je Anabi Olohun, ati Ojise – Olohun maa n je eda abara ni, eleyii si ni ilana ise ti Olohun nipa oro eda re, Olohun maa n gbe Ojise didi ninu won laarin eya won, eni ti koni yapa si won nibi nnkankan ayafi ibi wi pe Olohun da a lola pelu gbigba imisi ati ise riran, sugbon awon keferi tun lo jije eda abara ti awon Ojise je gege bi idi atako won si awon Anabi Olohun nibi jije Anabi Olohun won, gege bi Olohun se royin eleyi nipa ijo Nuh, Aad, Thamuuda, ati pe kiko lati gba ipepe ti awon Anabi Olohun pe won si kise tori nnkan kan bi ko se pe tori pe won je eda abara ni, pelu gbolohun Olohun ti O so pe:

"قَالَتْ رُسُلُهُمْ أَفِي اللّهِ شَكٌّ فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ يَدْعُوكُمْ لِيَغْفِرَ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرَكُمْ إِلَى أَجَلٍ مُّسَمًّى قَالُواْ إِنْ أَنتُمْ إِلاَّ بَشَرٌ مِّثْلُنَا تُرِيدُونَ أَن تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعْبُدُ آبَآؤُنَا فَأْتُونَا بِسُلْطَانٍ مُّبِينٍ {إبراهيم/10} قَالَتْ لَهُمْ رُسُلُهُمْ إِن نَّحْنُ إِلاَّ بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ وَلَكِنَّ اللّهَ يَمُنُّ عَلَى مَن يَشَاء مِنْ عِبَادِهِ وَمَا كَانَ لَنَا أَن نَّأْتِيَكُم بِسُلْطَانٍ إِلاَّ بِإِذْنِ اللّهِ وَعلَى اللّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ" {إبراهيم/11}

“Awon Ojise won so pe; ‘Se iyemeji kan n be nibi (bibe) Olohun, Olupile eda awon sanmo ati ile? O n pe yin nitori ki O le fori awon ese yin jin yin, ati nitori ki O le lo yin lara di gbedeke akoko kan” won wi pe: ‘Eyin ko je kini kan tayo abara bi iru wa, Eyin si fe se wa lori kuro nibi nnkan ti awon baba wa n josin fu. Nitori naa, e fun wa ni eri to yanju. * Awon Ojise won so fun won pe: “Awa ko je kini kan tayo abara bi iru yin Sugbon Olohun ni O n se oore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re, Ko si letoo fun wa lati fun yin ni eri kan afi pelu iyonda Olohun Ati pe, Olohun ni ki awon onigbagbo ododo maa gbara le.” (Suurah Ibroohim: 10 – 11)

Ati awon oro ti Olohun so nipa Fir’aona ati awon emewa re nigba ti won pe Anabi musa (ki Alaafia Olohun maa ba a) nigba ti won salaye idi atako ati idi lowo won si ise ti Anabi Musa (ki Alaafia Olohun maa ba a) je fun won. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"ثُمَّ أَرْسَلْنَا مُوسَى وَأَخَاهُ هَارُونَ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ * إِلَى فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَاسْتَكْبَرُوا وَكَانُوا قَوْمًا عَالِينَ * فَقَالُوا أَنُؤْمِنُ لِبَشَرَيْنِ مِثْلِنَا وَقَوْمُهُمَا لَنَا عَابِدُونَ" {المؤمنون 45/47}

“Leyin naa, A ran (Anabi) Musaa ati omo iya re (Anabi) Haaruun nise pelu awon ami Wa ati eri to yanju * (A ran won) si Fir’aon ati awon ijoye re, sugbon won se igberaga, won si je ijo to se motomoto lori awon eda. * Won wi pe: ‘Se ki awa gba abara meji bi iru wa gbo, nigba ti o je pe eru wa ni awon eniyan won” (Suurah al – mu’miinuun: 45-47)

 Eleyi ni isesi awon to maa n tako ise ipepe awon Ojise – Olohun, eleyi ni isesi awon eni anu, awon ti won je olupepe soju ona anu. Nipa bayii, eni to je ikeyin awon Anabi Olohun ati awon Ojise – Olohun ti i se Anabi Muhammad (ki Ike ati Ola maa ba a) naa kole jinna si pipade iru isesi yii, tori naa, awon kefere Quraish naa tele iru ojuona ti awon ti won siwaju rin, nipa pipe awon Ojise niro, Olohun ti Ola Re salaye eyi bayi pe:

"وَأَسَرُّواْ النَّجْوَى الَّذِينَ ظَلَمُواْ هَلْ هَذَا إِلاَّ بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ أَفَتَأْتُونَ السِّحْرَ وَأَنتُمْ تُبْصِرُونَ" {الأنبياء/3}

“Won fonufora ni, Awon ti won sabosi si fi oro ikoko (aarin ara won) pamo pe: ‘Se eyi je nkankan yato si abara bi iru yin ni? se eyin yoo tele idan, nigba ti eyin naa riran?” (Suurah al – Anbiyya: 3)

Nipa bayii, gbogbo awon Ojise – Olohun laiyo enikankan sile ki i se Olohun, kosi iroyin ti won fi le je Olohun lara won Kankan, Idi niyi ti Anabi Hisa (Ki Ike ati Ola Olohun maa baa a) fi mo ara re kuro nibi ohun ti won safiti sodo re nipa pipe e ni Olohun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِذْ قَالَ اللّهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ أَأَنتَ قُلتَ لِلنَّاسِ اتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَهَيْنِ مِن دُونِ اللّهِ قَالَ سُبْحَانَكَ مَا يَكُونُ لِي أَنْ أَقُولَ مَا لَيْسَ لِي بِحَقٍّ إِن كُنتُ قُلْتُهُ فَقَدْ عَلِمْتَهُ تَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِي وَلاَ أَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِكَ إِنَّكَ أَنتَ عَلاَّمُ الْغُيُوبِ * مَا قُلْتُ لَهُمْ إِلاَّ مَا أَمَرْتَنِي بِهِ أَنِ اعْبُدُواْ اللّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ وَكُنتُ عَلَيْهِمْ شَهِيدًا مَّا دُمْتُ فِيهِمْ فَلَمَّا تَوَفَّيْتَنِي كُنتَ أَنتَ الرَّقِيبَ عَلَيْهِمْ وَأَنتَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ" {المائدة 116/117}

“(E tun ranti) nigba ti Olohun so pe: ‘Iwo ‘Iisa omo moryam, se iwo ni o so fun awon eniyan pe: “e mu emi ati iya mi ni Olohun meji ti e oo maa josin fun leyin Olohun?” O so pe: ‘Mimo ni fun O, ko to fun mi lati so ohun ti emi ko letoo (lati so), Ti mo ba so bee, O kuku ti mo, iwo mo ohun ti n be ninu emi mi, emi ko si mo ohun ti n be ninu emi Re Dajudaju Iwo ni Olumo nipa awon ikoko * Emi ko so kini kan fun wi bi ko se ohun ti O pa mi ni ase re pe: ‘E josin fun Olohun, Oluwa mi ati Oluwa yin, ‘Emi je eleri lori won niwon igba ti mo n be laarin won Sugbon nigba ti O ti gbe mi (was sinu sanmo), Iwo ni Oluso lori won, Iwo si ni Arinu – rode gbogbo nnkan.” (Suurah al-Moo’idah: 116- 117)

 Anabi wa Muhammad (ki Ike ati Ola maa ba a) bakan naa le jinna si ara re pe ki awon iroyin to ye Olohun mase wa fun oun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُل لاَّ أَمْلِكُ لِنَفْسِي نَفْعًا وَلاَ ضَرًّا إِلاَّ مَا شَاء اللّهُ وَلَوْ كُنتُ أَعْلَمُ الْغَيْبَ لاَسْتَكْثَرْتُ مِنَ الْخَيْرِ وَمَا مَسَّنِيَ السُّوءُ إِنْ أَنَاْ إِلاَّ نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ" {الأعراف/188}

“So pe: ‘Emi ko ni agbara anfani tabi inira kan ti mo le fi kan ara mi ayafi ohun ti Olohun ba fe, Ti o ba je pe mo ni imo ikoko ni, emi iba ti ko ohun pupo jo ninu oore aye (si odo mi) ati pe aburu aye iba tii kan mi, ta ni emi bi ko se olukilo ati oniroo -idunnu fun ijo to ni igbagbo ododo.” (Suurah Al-A‘raaf: 188)

Jije omoniyan eda abara won je ki o se dandan ko maa sele si won iru nnkan to maa n sele si gbogbo eda abara patapat, bii, iki ti won o ku, won o ni maa be laye lo gbere, gege bi Olohun Adedaa se so pe:

"كُلُّ نَفْسٍ ذَآئِقَةُ الْمَوْتِ وَإِنَّمَا تُوَفَّوْنَ أُجُورَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فَمَن زُحْزِحَ عَنِ النَّارِ وَأُدْخِلَ الْجَنَّةَ فَقَدْ فَازَ وَما الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلاَّ مَتَاعُ الْغُرُورِ" {آل عمران/185}

“Emi kookan ni o maa to iku wo, A o si san yin ni esan yin ni ekunrere ni Ojo Ajinde. Nitori naa enikeni ti A ba mu jinna tefe si Ina, ti A si mu wo inu Ogba Idera, o kuku ti jere. Ki si ni igbesi aye tayo igbadun itanje.” (Suurah aali – Imroon: 185)

 Iru adanwo to maa n de ba awon elomira, lo si maa n de ba awon naa, nipa bayii adanwo awon aisan ati amodi a maa bawon, Gege bi o se sele si Anabi Ayuba (ki Alaafia Olohun maa ba a) adanwo ba alaafia ara re, lilo owo ati dukia re, lilo awon ara ile re ati omo re, fun idi eyi o se suru, o si se ifarada, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَأَيُّوبَ إِذْ نَادَى رَبَّهُ أَنِّي مَسَّنِيَ الضُّرُّ وَأَنتَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ * فَاسْتَجَبْنَا لَهُ فَكَشَفْنَا مَا بِهِ مِن ضُرٍّ وَآتَيْنَاهُ أَهْلَهُ وَمِثْلَهُم مَّعَهُمْ رَحْمَةً مِّنْ عِندِنَا وَذِكْرَى لِلْعَابِدِينَ" {الأنبياء 83/84}

“(E ranti Anabi) Ayyuub, nigba ti o pe Oluwa re pe: “Dajudaju owo inira ti kan mi, Iwo si ni Alaanu julo ninu awon alaanu * A si je ipe re. A mu gbogbo inira re kuro fun un. A tun fun un ni awon ebi re (pada) ati (alekun), ati iru won pelu won, (o je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon olujosin (fun Wa). (Suurah Al - Anbiyyaa: 83 - 84)

 Koda, won a maa ju won si inu ewon, gege bi won se ju Anabi Yusuf, (ki Alaafi Olohun maa ba) si inu ewon. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّن بَعْدِ مَا رَأَوُاْ الآيَاتِ لَيَسْجُنُنَّهُ حَتَّى حِينٍ" {يوسف/35}

 “Leyin igba ti won ti ri awon ami (pe Yusuf ko jebi esun), leyin naa, o han si won pe awon gbodo so o sinu ogba ewon titi di asiko kan na” (Suurah Al – Yusuff: 35)

Koda, won a maa le won jade kuro nile won, gege bi Olohun se royin eyi pelu gbolohun to so bayi pe:

"وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُواْ لِرُسُلِهِمْ لَنُخْرِجَنَّكُم مِّنْ أَرْضِنَآ أَوْ لَتَعُودُنَّ فِي مِلَّتِنَا فَأَوْحَى إِلَيْهِمْ رَبُّهُمْ لَنُهْلِكَنَّ الظَّالِمِينَ * وَلَنُسْكِنَنَّكُمُ الأَرْضَ مِن بَعْدِهِمْ ذَلِكَ لِمَنْ خَافَ مَقَامِي وَخَافَ وَعِيدِ" {إبراهيم/14}

Awon ti won siagbagbo wi fun awon Ojise won pe: ‘Dajudaju awa yoo le yin jade kuro ni ori ile wa, tabi ki e kuku pada sinu esin wa’ Nigba naa, Oluwa won fi imisi ranse si won pe: “Dajudaju Awa yoo pa awon alabosi run. * Dajudaju Awa yo si fun yin ni ibugbe lori ile leyin won, Iyen wa fun eni ti o ba beru iduro (niwaju) Mi, ti o tun beru ileri Mi” (Suurah Ibroohim: 13– 14)

 Won a si maa pa won, nigba miran, gege bi Olohun se royin eyi nipa awon Anabi Olohun kan ti won je Anabi awon omo isireli, awon Anabi Olohun ti won pa lati owo awon kefere omo Isireli. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَفَكُلَّمَا جَاءكُمْ رَسُولٌ بِمَا لاَ تَهْوَى أَنفُسُكُمُ اسْتَكْبَرْتُمْ فَفَرِيقاً كَذَّبْتُمْ وَفَرِيقاً تَقْتُلُونَ" {البقرة/87}

“Se gbogbo igba ti Ojise kan ba wa ba yin pelu ohun ti okan yin ko fe ni e o maa segbereaga? E si pe apa kan (awonAnabi) ni opuro, e si n pa apa kan!”

 (Suurah al – Baqoorah: 87)

Ati nitori adamo won, ti o je adamo ti eda abara, tori pe awon naa maa n wa bukata si gbogbo n ti awon eda abara maa n wa bukata si, nipa bayi, won a maa jeun, won a si maa mu, won a maa ba awon eniyan se asepo, won a maa rerin, won a maa sunkun, won a maa dunnu, won a si maa banuje. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَما أَرْسَلْنَا قَبْلَكَ مِنَ الْمُرْسَلِينَ إِلاَّ إِنَّهُمْ لَيَأْكُلُونَ الطَّعَامَ وَيَمْشُونَ فِي الأَسْوَاقِ وَجَعَلْنَا بَعْضَكُمْ لِبَعْضٍ فِتْنَةً أَتَصْبِرُونَ وَكَانَ رَبُّكَ بَصِيرًا" {الفرقان/20}

“Awa ko ran awon Ojise nise siwaju re afi ki won maa jeun, ki won si maa rin ninu oja A ti fi apa kan yin se adanwo fun apa kan, nje eyin yoo se suuru bi? Oluwa re si je Oluriran” (Suurah al - Furqoon: 20)

 Nigba ti awon keferi omo Isireli koja ala nipa Hiisa (ki Alaafia Olohun maa ba a) ti won se afiti jije Olohun sodo re, Olohun ba salaye jije eda abara re to je, ati wiwa bukata si gbogbo ohun ti eda abara maa n wa bukata si ninu ounje, ohun mimu, a si maa sele sawon naa awon jijade awon asekubo ounje ati mimu kuro lara, latari ito tito, igbe yiya, oogun sise. Olohun ti o mo julo so pe;

"مَّا الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ إِلاَّ رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِ الرُّسُلُ وَأُمُّهُ صِدِّيقَةٌ كَانَا يَأْكُلاَنِ الطَّعَامَ انظُرْ كَيْفَ نُبَيِّنُ لَهُمُ الآيَاتِ ثُمَّ انظُرْ أَنَّى يُؤْفَكُونَ {المائدة/75}

“Ki ni Mosiih bi ko se Ojise kan, Awon Ojise si ti wa siwaju re Olododo si ni iya re, (Awom mejeeji) won a maa je ounje, Wo bi A ti se n se alaye awon aayah naa, Leyin naa, wo o, bawo ni won se n da adapa iro? (Suurah al – Mooi’dah: 75)

 Won a si maa fe iyawo, won a maa ni omo ati omo omo. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلاً مِّن قَبْلِكَ وَجَعَلْنَا لَهُمْ أَزْوَاجًا وَذُرِّيَّةً وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأْتِيَ بِآيَةٍ إِلاَّ بِإِذْنِ اللّهِ لِكُلِّ أَجَلٍ كِتَابٌ" {الرعد/38}

 “Dajudaju A ti ran awon Ojise kan nise siwaju r, a si fun won ni awon iyawo ati awon omoomo, Ko letoo fun Ojise kan lati mu ami kan wa ayafi pelu ase Olohun, Gbogbo isele lo ni akosile” (Suurah a-r-Ra’d: 38)

 Won a maa se adayanri pe ipepe awon w a fun Olohun nikansoso, won ki i si je ki awon anfaani aye lupo mo ipepe won, nitori naa, won o beere owo oya Kankan lowo awon eniyan won lori ipepe won bi ko se pe won maa n reti esan lodo Olohun, gbogbo won patapata si maa n ba awon eniyan soro gege Olohun ti Ola Re ga ti o sig bon – ngbo se so pe:

"قُلْ مَا سَأَلْتُكُم مِّنْ أَجْرٍ فَهُوَ لَكُمْ إِنْ أَجْرِيَ إِلاَّ عَلَى اللَّهِ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ" {سبأ/47}

“So pe: ‘emi ko bi yin leere owo – oya kan, ti o je ti yin, Ko si owo oya mi (ni odo eni kankan) afi ni odo Olohun, Oun si ni Arinu – rode ikoko” (Suurah Saba: 47)

 Fun idi eyi, nigba ti awon Ojise Olohun (ki Ike ati Ola Olohun to lola julo maa ba won) ba je eni ti o le jinan si ara won yiyapa si eda abara ati pipe anfaani ati inira mo ara won, a je pe dandan ni ki o senmo fun awon eniyan kan ti won mu awon eda abara bii ti won ni orisa ti won o maa sin won gege bi won se n sin Olohun, ti won si tun n ladisokan pe anfaani ati inira maa n wa latowo won, bee si ni awon ti won n sin yii o ku ni won, koda won kagara ju bi awon eniyan to n sin won se kagara nibi sise anfaani fun ara won lo. Ododo loro Olohun Oba ti O tobi julo ti o sope:

"فَلَوْلاَ نَصَرَهُمُ الَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِ اللَّهِ قُرْبَانًا آلِهَةً بَلْ ضَلُّوا عَنْهُمْ وَذَلِكَ إِفْكُهُمْ وَمَا كَانُوا يَفْتَرُونَ" {الأحقاف/28}

“Awon orisa ti won mu ni ohun ti o maa mu won sunmo (igbala) leyin Olohun, won ko se ran won lowo? Rara (ko le si aranse fun won) Won ti dofo mo won lowo, Iyen si ni (orisa) iro won ati ohun ti won n da ni adapa iro.” (Suurah al – Ahqoof: 28)

 

 

 

GBOGBO AWON ANABI OLOHUN PATAPATA LO MAA N PEPE SIBI IJOSIN FUN OLOHUN NIKAN SOSO

            Pi pepe sibi imu Olohun lokan, ati sise afomo ijosin fun Olohun, ati wiwa isora kuro nibi ebo sise ni ipepe gbogbo awon anabi Olohun ati Ojise – Olohun fun awon eniyan won tolohun ran won si, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلاَّ نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لاَ إِلَهَ إِلاَّ أَنَا فَاعْبُدُونِ" {الأنبياء/25}

“Awa ko ran ojise kan nise siwaju re afi ki A fi imisi ranse si i pe: “Dajudaju ko si Olohun ti Ijosin to si afi Emi (Olohun), Nitori naa, e josin fun Mi” (Suurah al – ‘Annbiyaa’: 25)

 Awon Anabi Olohun (ki Alaafia Olohun maa ba won) ki i pe won eniyan sibi pe ki won o maa sin awon, tabi ki won maa sin elomiran to yato si awon, bi ko se pe won je eni ti o maa n sora gidigidi fun eleyi, gege bi Olohun ti Ola Re ga se so pe:

"مَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُؤْتِيَهُ اللّهُ الْكِتَابَ وَالْحُكْمَ وَالنُّبُوَّةَ ثُمَّ يَقُولَ لِلنَّاسِ كُونُواْ عِبَادًا لِّي مِن دُونِ اللّهِ وَلَكِن كُونُواْ رَبَّانِيِّينَ بِمَا كُنتُمْ تُعَلِّمُونَ الْكِتَابَ وَبِمَا كُنتُمْ تَدْرُسُونَ * وَلاَ يَأْمُرَكُمْ أَن تَتَّخِذُواْ الْمَلاَئِكَةَ وَالنِّبِيِّيْنَ أَرْبَابًا أَيَأْمُرُكُم بِالْكُفْرِ بَعْدَ إِذْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ" {آل عمران 79/80}

“Ko letoo fun abara kan nigba ti Olohun ba fun un ni tira, idajoati ipo Anabi, leyin naa ki o maa so fun awon eniyan pe, “e je erusin fun mi leyin Olohun” Sugbon (o maa so pe) ‘e je olujosin fun Oluwa (ki e si maa fi eko Re ko awon eniyan) nitori pe e je eni ti n ko eko (nipa esin). * (Anabi kan) ko si n ii pa yin ni ase pe ki e so awon molaaika ati awon Anabi di oluwa, Se o maa pa yin ni ase sise aigbagbo leyin ti e ti je musulumi ni?” (Suurah aali – Imroon: 79 - 80)

Anabi Nuh, to je Ojise Olohun akooko lo egberun – un odun odin aadota lodo awon eniyan re, to si n pe won sibi ijosin fun Olohun, ati gbigbe Gbogbo nnkan to ba ti ko imorogun mo Olohun sinu ju sile. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَى قَوْمِهِ فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُواْ اللَّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَهٍ غَيْرُهُ إِنِّيَ أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ" {الأعراف/59}

“Dajudaju A ran (Anabi) Nuuh si ijo re. O si so pe; ‘Eyin ijo mi, e josin fun Olohun, Eyin ko si ni olohun kan ti ijosin to si leyin Re, Dajudaju emi n beru iya ojo nla lori yin” (Suurah Al – a-raaf: 59)

 Bakan naa Anabi Ibrohim, eni ti o je baba awon Anabi Olohun (ki Alaafia Olohun maa ba a) naa wa sisin Olohun ni okansoso lai mu orogun mo On lowo awon eniyan re. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِبْرَاهِيمَ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاتَّقُوهُ ذَلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ * إِنَّمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ أَوْثَانًا وَتَخْلُقُونَ إِفْكًا إِنَّ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لاَ يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقًا فَابْتَغُوا عِندَ اللَّهِ الرِّزْقَ وَاعْبُدُوهُ وَاشْكُرُوا لَهُ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ {العنكبوت 16/17}

“(Ranti Anabi) Ibroohiim, Nigba ti o so fun awon eniyan re pe: “e josin fun Olohun, Ki e si paya Re, Iyen ni o dara ju lo fun yin ti eyin ba mo. * E kan n josin fun awon orisa leyin Olohun, E si n da adapa iro, Dajudaju awon ti e n josin fun leyin Olohun Won ko ni ikapa arisiki kan fun yin, E wa arisiki si odo Olohun, Ki e josin fun Un, Ki e si dupe fun Un, Odo Re ni won yoo da yin pada si” (Suurah Ankabuut: 16 – 17)

 Ipepe Huudu (Ki Alaafia Olohun maa ba a) naa fun awon eniyan re ni imu – Olohun – lokan ati ai morogun Kankan mo Olohun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِلَى عَادٍ أَخَاهُمْ هُودًا قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُواْ اللّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَهٍ غَيْرُهُ إِنْ أَنتُمْ إِلاَّ مُفْتَرُونَ" {هود/50}

“(Eni ti A ran) si ijo ‘Aad ni arakunrin won, (Anabi) Huud, O so pe: ‘Eyin ijo mi, e josin fun Olohun, Eyin ko si ni olohun kan ti ijosin to si leyin Re eyin ko si je kini kan bi ko se aladapa iro” (Suurah Huud: 50)

Ipepe Anabi Soolih (ki Alaafia Olohun maa ba a) naa fun awon eniyan re ni mimu Olohun lokan ati ai morogun Kankan mo Olohun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِلَى ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَالِحًا قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُواْ اللّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَهٍ غَيْرُهُ" {هود/61}

“(Eniti ti A ran) si Ijo Thamuud ni arakunrin won (Anabi Solih) o So pe: ‘Eyin ijo mi, e josiin fun Olohun, Eyin ko si ni olohun kan ti ijosin to si leyin Re” (Suurah Huud: 61)

Anabi Musa (ki Alaaafia Olohun maa ba a) leyin igba ti Olohun la a ati awon eniyan re lowo Firiaon ati awon emewa re, awon eniyan ni ko pese olohun ti yoo se e ri, ti awon o maa sin, o si salaye igbeyin buburu to wa fun eni to ba se be e, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَآئِيلَ الْبَحْرَ فَأَتَوْاْ عَلَى قَوْمٍ يَعْكُفُونَ عَلَى أَصْنَامٍ لَّهُمْ قَالُواْ يَا مُوسَى اجْعَل لَّنَا إِلَهًا كَمَا لَهُمْ آلِهَةٌ قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ تَجْهَلُونَ * إِنَّ هَؤُلاء مُتَبَّرٌ مَّا هُمْ فِيهِ وَبَاطِلٌ مَّا كَانُواْ يَعْمَلُونَ * قَالَ أَغَيْرَ اللّهِ أَبْغِيكُمْ إِلَهًا وَهُوَ فَضَّلَكُمْ عَلَى الْعَالَمِينَ {الأعراف 138/140}

“A mu awon omo Isroo’iil la agbami okun ja. Nigba naa, won pade awon ijo kanti suru bo awon orisa won, Wo si wi pe:: ‘Iwo Musa, gbe olohunkan kale fun wa gege bi awon (wonyi) se ni awon olohun, (Anabi) Musa so pe: ‘Dajudaju eyin ni ijo alaimokan. * Dajudaju awon wonyi maa parun lori ohun ti won n se (yii), O fo si ni ohun ti won n se nise.” * (Anabi) Muusaa so pe: “Se ki emi tun ba yin wa olohun kan ti eyin yoo maa josin fun leyin Olohun ni? Oun si ni O soore ajulo fun yin lori awon eda (asiko yin)” (Suurah: 138 – 140)

 Anabi Hisa (ki Alaaafia Olohun maa ba a) naa nigba ti won gbe e dide si awon kefere omo Isireli wi pe ki o pe won sibi ododo ati imu Olohun lokan, ti Olohun ti o mo ohun to wa lokan si n bi leere, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِذْ قَالَ اللّهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ أَأَنتَ قُلتَ لِلنَّاسِ اتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَهَيْنِ مِن دُونِ اللّهِ قَالَ سُبْحَانَكَ مَا يَكُونُ لِي أَنْ أَقُولَ مَا لَيْسَ لِي بِحَقٍّ إِن كُنتُ قُلْتُهُ فَقَدْ عَلِمْتَهُ تَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِي وَلاَ أَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِكَ إِنَّكَ أَنتَ عَلاَّمُ الْغُيُوبِ * مَا قُلْتُ لَهُمْ إِلاَّ مَا أَمَرْتَنِي بِهِ أَنِ اعْبُدُواْ اللّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ وَكُنتُ عَلَيْهِمْ شَهِيدًا مَّا دُمْتُ فِيهِمْ فَلَمَّا تَوَفَّيْتَنِي كُنتَ أَنتَ الرَّقِيبَ عَلَيْهِمْ وَأَنتَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ" {المائدة 116/117}

 “(E tun ranti) nigba ti Olohun so pe: ‘Iwo ‘Iisa omo moryam, se iwo ni o so fun awon eniyan pe: “e mu emi ati iya mi ni olohun meji ti e oo maa josin fun leyin Olohun?” O so pe: ‘Mimo ni fun O, ko to fun mi lati so ohun ti emi ko letoo si (lati so), Ti mo ba so bee, O kuku ti mo, iwo mo ohun ti n be ninu emi mi, emi ko si mo ohun ti n be ninu emi Re. Dajudaju Iwo ni Olumo nipa awon ikoko * Emi ko so kini kan fun won bi ko se ohun ti O pa mi ni ase re pe: ‘E josin fun Olohun, Oluwa mi ati Oluwa yin, ‘Emi je eleri lori won ni iwonba igba ti mo n be laaarin won, Sugbon nigba ti O ti gbe mi (wa sinu sanmo) Iwo ni Oluso lori won Iwo si ni Arinu – rode gbogbo nnkan.” (Suurah al-Moo’idah: 116- 117)

 Ati Anabi Muhammad (ki Ike ati Ola maa ba a) ti o je ikeyin awon Anabi Olohun, ipepe ti e naa ni ipepe si bi imu – Olohun – lokan ati gbigbe ohun to ba yatosi ju sile, ninu awon ebo ati orisa (gbigbe igi lere), Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا النَّاسُ اعْبُدُواْ رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ" {البقرة/21}

“Eyin eniya, e josin fun Oluwa yin, eni ti O da eyin ati awon ti won siwaju yin, ki e le sora (fun iya Ina)” (Suurah al – Baqoorah: 21)

 

 

AWON OFIN ATI AWON OJU ONA AYE – ODE ONI

Ododo ni oro Olohun ti      O tobi ti o so pe:

"وَإِن تُطِعْ أَكْثَرَ مَن فِي الأَرْضِ يُضِلُّوكَ عَن سَبِيلِ اللّهِ إِن يَتَّبِعُونَ إِلاَّ الظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلاَّ يَخْرُصُونَ" {الأنعام/116}

“Ti o ba tele opolopo awon ti n be lori ile, won maa si o lona nibi esin Olohun, Won ko tele kini kan bi ko se aroso, won ko se nkankan ayafi iro pipa” (Suurah al – Ani’aam: 116)

 Ti aba yara wo awon esin ati awon oju ona ti itankale won po ju, a o rip e opolopo ninu re ni ko ba laakaye mu, nitori imu orogun mo Olohun ti o wa ninu re, ati gbigbe afomo fun awon eda Olohun, O maa n wa nibe awon ofin to n pepe si awon iwa eleyin, ati kiko awon iwa aida fun ni, gbogbo eni to ba n ka a, lo maa lagbara ati le fa iyen yo latari ohun ti Olohun ba bun un lebun opolo ti yio fi se iyato laarin asise ati oro ti o se deede, bakan naa laarin ohun to ba opolo mu ati ohun ti ko ba opolo mu, bakan naa ti o tun le se iyato laarin agbekale oro to dara ati agbekale oro ti ko dara.

 

At – Taorah:

Eyi ni tira ti awon Yahuud n lo fun esin loni, lona atowoda ati imu Olohun ni meji nitoripe won n se adisokan pe Uzaeru je omo Olohun, Olohun lodo won ki i se eni ti won so kuro nibi asise bi ko se pe olohun ti o maa n se asise o maa n gbe ola felomiran ju ara re lo, a maa sabamo, a si maa pase ole jija, a maa se eyameya, o si je olohun omo Isireli nikan ni, pelu idi eyi lo si fi je pe ota ni olohun won je fun awon elomiran, Gege bi o se je pe won maa n ladisokan pe awon ni eniyan Olohun eni esa, awon eniyan miiran kere si awon nibi jije eni Olohun, ati pe eni ti iya re ko ba je Yahuund kole ni agbara ki o je Yahuud, nipa bayii, won so o di esin to je pe awon nikan lo wa fun, kosi fun elomiran to yato sawon, fun idi eyi, koye ko je esin agbaye ti gbogbo eda abara o maa sin, gege bi won se lero pe awon elesin Yahuudi je abala kan ninu Olohun, Giga Olohun tayo ohun ti won n so, ti elomiran ti ki se elesin Yahuudi ba na Yahuudi, loju won yio da bi eni ti o na giga Olohun, O je esin kan ti won mopa lori atako ati adisokan buburu si awon miiran to yato si won ninu awon orisirisi iran, nipa bayi o leto ninu esin won ki won maa gba eto ara won ni ona eeru fun ara won, o le jija laarin ara won, itanje laarin ara won, iro pipa mo ara won, yiya ara won lowo ele, ati ijeri iro tako eni ti o je elesin miiran, tori wipe ninu igbagbo won ni pe awon eni ti ki I se Yahuudi maa n da gege bii awon eran-osin, Al – Qur’aan si ti gbe e wa pe eleyii je ogidi iro latowo awon Yahuudi, Olohun ti Ola re ga so pe:

"وَقَالَتِ الْيَهُودُ وَالنَّصَارَى نَحْنُ أَبْنَاء اللّهِ وَأَحِبَّاؤُهُ قُلْ فَلِمَ يُعَذِّبُكُم بِذُنُوبِكُم بَلْ أَنتُم بَشَرٌ مِّمَّنْ خَلَقَ يَغْفِرُ لِمَن يَشَاء وَيُعَذِّبُ مَن يَشَاء وَلِلّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ" {المائدة/18}

“Awon yehuudi ati nasaara wi pe: ‘Awa ni omo Olohun ati ololufe Re’ So pe: Ki ni o fa a nigba naa ti (Olohun) se n fi ese yin je yin niya?” Rara (ko ri bi e se wi amo) abara ni yin ninu awon ti (Olohun) seda, (Olohun) yoo se aforijin fun eni ti O ba fe, O si maa je eni ti O ba fe niya, Ti Olohun ni ijoba awon sanmo, ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji, Odo Re si ni abo wa” (Suurah: al – moo’idah 18)

 ki a lo mo pe opolopo awon yahuudi ode oni je awon toni ipo ati oro, won o ni abatan pelu awon omo Isireli (Hibraheen) ti aye ijoun, awon ti won sewa latodo Ibrahim (ki Alaafia Olohun maa ba a) ati latodo omo re ti a mo si Isireli ti i se Yaaquub (ki Alaaafi Olohun maa ba a) nigba to se pe wonje asawo ninu awon eniyan to wa lori’le, awon to se pe won wo inu esin yahuudi nitori itanmo ti won ni si aye, Sugbon awon Yahuud ipile ni awon to se wa lati idile Isireli ti i se Yaquub (ki Alaafia maa ba a) tori idi eyi, awon Yahuudi to seku won n lero pe awonYahuudi asawo wa ni ipo to rele pupo.

 

AL – INJIIL:

Eleyii ni ohun ti awon Nasoorah n lo fun esin won loni, eleyii ti o gba ipele orisirisi koja, ninu orisirisi itan, eyi ti won muwa lati ipo iranse lati odo Olohun, titi de ibi esin atowoda ati esin mimu Olohun ni meji, ipa pataki lo wa fun awon Oloselu ati awon alagbigba lori ayipada yii, nigba ti o se pe igbagbo won ni meta loka, Olohun Baba, Olohun omo, Olohun emi mimo, eleyii si ni won n pe ni metalokan, tabi eyokan ni meta, won si yapa si ara won lori e ni iyapa kan to foju han, fun ai lagboye re, igbagbo ijo kan koni ti ijo miiran, idi eyi, Olohun ti Ola re ga si ti se idajo aigbagbo won lapapo, ti won ko ba jawo nibi ohun ti won n so to je oro imu orogun mo Olohun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُواْ إِنَّ اللّهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ وَقَالَ الْمَسِيحُ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اعْبُدُواْ اللّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ إِنَّهُ مَن يُشْرِكْ بِاللّهِ فَقَدْ حَرَّمَ اللّهُ عَلَيهِ الْجَنَّةَ وَمَأْوَاهُ النَّارُ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ" {المائدة/72}

“Won kuku ti di keferi, awon ti won wi pe: Dajudaju Olohun ni mosiih omo moryam’ mosiih si so pe: ‘Eyin omo Isroo’iil, e josin fun Olohun, Oluwa mi ati Oluwa yin, Dajudaju enikeni ti o ba ba Olohun wa egbera Olohun ti se Ogba Idera ni eewo fun un. Ina si ni ibugbe re, ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi”

(Suurah: al – moo’idah 82)

Gege bi O se je pe ofin esin ti won tori re gbe Anabi Hiisa dide (ki Alaafia Olohun maa ba a) ni ati pe awon to sonu ninu omo Isireli pada, ti won je awon to wa leyin Anabi Musa (ki Alaafia Olohun maa ba a) kii se pe won gbe e dide nitori gbogbo eda abara lapapo gege bi o se salaye ninu Al – Injil Matta eyi ti O ni alaafia (6, 10, 5) pelu oro re:

“E ma se doju ko awon oju ona awon ijo ijo

E ma se wo awon ilu samiriyu, Bi ko se pe e maa lo fun ra yin ti e o fi de ibi aguntan omo Isireli to sonu”

Ibi yii lo ti han si wa pe agbekale re je ti ofin iborisa nitoripe o won mu Anabi Hiisa (ki Alaaafia Olohun maa ba a) ati iya re ni Olohun meji ti won si n sin awon mejeeji yatosi Olohun, toun ti bo se je pe ipepe Anabi Hiisa ni ipepe imu Olohun – lokan ati aisi orogun pelu Olohun, gege bi Olohun se royin bayii:

"قَالَ اللّهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ أَأَنتَ قُلتَ لِلنَّاسِ اتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَهَيْنِ مِن دُونِ اللّهِ قَالَ سُبْحَانَكَ مَا يَكُونُ لِي أَنْ أَقُولَ مَا لَيْسَ لِي بِحَقٍّ إِن كُنتُ قُلْتُهُ فَقَدْ عَلِمْتَهُ تَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِي وَلاَ أَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِكَ إِنَّكَ أَنتَ عَلاَّمُ الْغُيُوبِ * مَا قُلْتُ لَهُمْ إِلاَّ مَا أَمَرْتَنِي بِهِ أَنِ اعْبُدُواْ اللّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ وَكُنتُ عَلَيْهِمْ شَهِيدًا مَّا دُمْتُ فِيهِمْ فَلَمَّا تَوَفَّيْتَنِي كُنتَ أَنتَ الرَّقِيبَ عَلَيْهِمْ وَأَنتَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ {المائدة 116/117}

“(E tun ranti) nigba ti Olohun so pe: ‘Iwo ‘Iisa omo moryam, se iwo ni o so fun awon eniyan pe: “e mu emi ati iya mi ni olohun meji ti e oo maa josin fun leyin Olohun?” O so pe: ‘Mimo ni fun O, ko to fun mi lati so ohun ti emi ko letoo si (lati so), Ti mo ba so bee, O kuku ti mo, iwo mo ohun ti n be ninu emi mi, emi ko si mo ohun ti n be ninu emi Re. Dajudaju Iwo ni Olumo nipa awon ikoko * Emi ko so kini kan fun won bi ko se ohun ti O pa mi ni ase re pe: ‘E josin fun Olohun, Oluwa mi ati Oluwa yin, ‘Emi je eleri lori won ni iwonba igba ti mo n be laaarin won, Sugbon nigba ti O ti gbe mi (wa sinu sanmo) Iwo ni Oluso lori won Iwo si ni Arinu – rode gbogbo nnkan.” (Suurah al-Moo’idah: 116- 117)

Awon Nasoorah ti mu eyi topo ninu awon esin ati adisokan to ti n be tele siwaju esin Nasrooh, nipa bayi esin Nasrooh lapa nibe, eleyi si je esin kan toti n be tipetipe nilu faris, siwaju bibi Anabi (ki Ike ati Ola Olohun maa ba a) ni ogorun odun mefa, eyi ti o ko itan to jo itan ounje ale Oluwa, bakan naa ni won mu lara ijosin awon ijo hundus, metalokan lawon naa gbagbo nitoripe Olohun ni oruko meta lodo won, awon oruko naa ni wonyii “Fashanu” ti o tumo si Oluso, “Saefah” ti o tumo si “Olupanire” ati “barihamo” Olumuni maa be, Gege bi won ti se mu igbagbo Alagbelebu lati le ri ihadanu ese nibi asise, Riri aye sa, aimafe yawo, yiyo ara enikuro nibi ife owo nitori ati le wo joba orun, gegebi bi o ti se je pe won yi awon adisokan ibe die, Bakan naa won tun yi die lara awon irori AL – BUDHIYYAH to koko wa fun bii ogorun odu marun – un siwaju Nasroniyyah (Christinanity) nitoripe O salaye imo nipa bi awon esin se sunmo ara won nibi jijora, ati riri amulo isesi Buudha pe ohun ni isesi Al – Masiih (ki Alaafia Olohun maa ba a) ati pe ipo ati isesi ti won gba fi bi Al – Masiih pelu isemi Al – Masiihi ati isesi ti Budha naa la koja wa lara ohun to mu ki esin Nasrooniyah (Christanity) nipon nibi riri opolopo ilapa adisokan AL – Budhaiyyah ninu re, gege bii o se je pe adisokan awon oni Bibeli (Biblical Ideology) ijoun naa se ropo mo ara won, nitoripe idajo ofin “Baalu” ti i se Olohun Oorun naa jo ti idajo ofin Al – Masiih (ki Alaafia Olohun maa ba a), ibi yi lati ri bi ayipada se ba Al – Injiil ati bi awon adisokan imaa sin eda Olohun se yiwo inu esin Nasooroh eleyii to se pe kosi ninu irisi ati ilanan Al – Injiil ni ipile, to je eyi ti Anabi Hiisa (ki Alaafia Olohun maa ba a) mu wa lati odo Olohun Olutoju gbogbo eda.

 

AWON IJO INDUUS:

Akojopo re pari leyin ti o ti la awon ipele togun koja, de bi wi pe a o mo oludaisle kan pato fun esin naa, A ko si tun mo akowe agba to ko o, O je alupo imo filosofi ile, India nikan ni ohun ti a mo.

Ninu At – Taorha (To je ti Yahuudi) ati Al – Injiil (To je ti Nasooroh) alatowoda, akojopo re n je eyi to ko awon adisokan imaa sin eda Olohun si inu, leyin ti agbekale oro re ko dara, bakan naa ti ko tun ba opolo mu, bii sinsin awon igi, awon okuta, awon obo, sisafomo awon Maluu eleyi ti o fi dipe Maluu gan n gbadun gbigbe e sipo nla, won tun gbe ere fun un si inu ile lati le ma josin fun un , ati awon ibugbe ati awon papa ati gbagede fun ijosin Maluu, O si tun leto si ohun ti opolopo eda abara maa n rankan lodo awon elesin yii, nitoripe o ni itusile ki o maa soro bi eniyan, bakan naa eewo si tun ni ki won pa a tabi ki won fi suta se e, ti o ba si ku won a sin pelu ilana ijosin won, Awon ijo Induus tun ni afikun si imaa sin eda Olohun latari pe won maa n se eyi ti won fi maa n korira ara won, eyi ti o pin awujo won si ipele orisirisi, Apa kan won maa n fi apa kan miiran se yeye , eleyi ti won fi di eni ti yoo maa gunri kuro nibi awon ojuse omoniyan si ara won, bakan naa ti won a tun fi maa gunri kuro nibi deede toye awujo, ninu ohun ti ntokasi pe isesi won yi jinna tefe si imisi ti o maa n wa latodo Olohun.

 

AWON IJO BUDHIYYAH:

Eleyi ni eto opolo ti won gbekale lati fi se atupale ohun ti o ye ki esin ni gege bi eto iwa, nitoripe won fe gbekale gege bi eto atun -iwase, ona Arojinle ti won mo pa lori iwoye imo opolo, awon idanileko re ki i si i se imisi bi ko se pe o je awon irori kan ati awon adisokan kan nipa agbekale esin, Esin yii jeyo nile India leyin esin Induusiyyah ni ogorun – marun odun si ki won o to bi Annabi Hiisa (ki Ola Olohun maa ba a), leyin iku Oludasile re ti a mo si “Sadiarithau Uthama” ti a maa n dape ni “Buudha” 480 – 560 B.B. Oyipada di awon adisokan ibaje ti o mu imaa sin eda Olohun, awon elesin Buudhiyah yi ni adisokan pe Buudha je omo Olohun, oun si nni eni afomo ninu eda abara ni gbogbo ona, ati wi pe oun ni eni ti o ti bawon ko gbogbo ese won lo, Ninu ohun ti o tokasi pe won nsin eda Olohun, ni gbolohun won ti won maa n so bayi pe: Bi Buudha se wole ti okan lara awon Al – Hayyakil gbogbo awon orisa kan forikanle fun un,won ni idi niyi ti awon elesin Buudha fi maa n kirun lati le forikanle fun Buudha, won gbe ere re, won si lo gbe si ibi aye ijosin won ati awon ibugbe won to wa fun gbogbo apapo won, won lero pe oun ni o maa mu ki awon wo Alujannah.

 Lara awon idanilekoo awon ijo Buudhiyah ni awon iwa eleyi bii: Pipepe si ife, amojukuro, ibagbepo daadaa, imaa se itore aanu fun awon Alaini, lara re tun ni ipepe si jije Alaini fe yawo, ati gbigbe oro nini jusile, aye imaa yanni je, ati gbigbe emi si ipo yiyera, sisa kuro fun obinrin ati sisora fun awon obinrin, owo, ojukokoro. Nibi jijinaa si igbeyawo ati sisoro fun ohun to ba ti yapa si adamo emi eda abara, eyi ti Olohun pase sise re lori ife si gbogbo nkan ti idanileko esin naa ko fun ni, awon gan – an na si maa jewo pe iwe akosile ofin esin awon ki i se eyi to sokale latoke sanmo, ati pe won kan je awon agbekale oro kan ti won safiti re sodo Buudha, tabi akosile itan kan nipa awon ise re ti awon olutele e ko sile, Eleyi si je ko han pe adisokan to je ti mimu orogun molohun ni, ki i se adisokan sisin Olohun Adedaa, nipa bayii agbekale kan ti o je ti imo opolo ati awon opolo kan to je ti tomoniyan ni, eleyii ti oludaisl re ati awon olutele e leyin re je pe awon ni won hun ni aye igba kan ti o fi de ipo ti o wa ni isin yi.

 

AWON S-SHIIKH:

Eleyii ki i se esin ki i si i se oju ona ijosin biko se pe won je okan ninu igbese atunse esin, eyi to se pe Islam lapa nibe, igbiyanju lati so awon adisokan ati awon esin ti o wa lori ile di okan naa ni ojuse won, awon Janmoh elesin Unuud ni won daa sile, awon wonyi han ni ipari ogorun keedogun odun si ibere ogorun odun kerindinlogun leyin bibi Anabi Hiisa, ti won n pepe sinu esin tuntun ti o kojo laarin islaam ati Undusiyya labe Akole “Kosi Unduusi kosi awon musulumi” sugbon esin naa ko se konge ero re yii, o mu aimokan wo inu Islaam, ati awon adisokan Islaam ati awon eko re, o wa gege bi ona anu kuro nibi oju ona to ni alaafia. Tori pe kani awon elesin yii mo pe awon esin gbodo je n ti yio o ni imisi kan ti n wa lati odo Olohun, Kosi si aye fun igbiyanju omoniyan lori imu ofin wa ati kiko ofin esin jo latara orisirisi awon esin ati awon liana, nitori ati le ri asunmo laarin won. Bakan naa mimu adisokan ti gbogbo okan papo le lori, leyin naa, won so awon adisokan yii di irinse lowo awon ara ilu (England) ile Geesi ko fi je pe won maa lo lati fi ba won fi wa aabo lori awon ohun to fe dawon pada seyin, ti n pepe lo sibi yiyo won jade kuro ni India, Nitori pe ijoba amunisin awon (England) ile Geessi ni ilapa nla nibi igbalaaye eto As – siikh lona ara oto pupo, debi wi pe o je ki awon ara ile Geesi ri irorun ara oto lodo gbogbo eni ti n gbe abala aye yen lorile aye, debi wi pe omo ogun ile India to ju (20%) ida ogun ninu ogorun lo lo ti ni irisi ara ile (Britain) Geesi.

 O wa han si wa nibi yii wi pe agbekale kan ti won gbero atunse latari idasile re ni As – siikh, sugbon eto yen ko ni aseyori nitoripe o pade awon ti won dapo mo ti won, ti won si maa mu idagbasoke ba a latara awon ara ilu Geesi Amunisin, awon ti won ri ohun elo ti yio je ki imunisin rorun si fun awon ninu agbekale As siikh, ti yio fi rorun fun awon lati maa je gaba lori awon ilu, ati lori wiwo esin Islaam eyi ti o je esin to ni alaafia. Nigba ti o si je pe ko rorun ki ododo ki o papo mo iro, imu Olohun – lokan naa ko le kojo po mo imu orogun mo Olohun, ni kofi rorun lati ri Islaam wo.

 

ESIN ISLAAM:

Esin Islaam ni awon ofin esin to n wa lati sanmo, ti o sokale keyin, Ojise re naa si ni ikeyin awon Anabi Olohun ati awon Ojise Olohun, kosi Ojise tabi Anabi miran leyin re, esin naa si tun ni ikeyin awon esin, koni si esin tabi ofin esin miran mo leyin re, titi ti asiko opin Aye o fi de, nitoripe oun ni won fi pe esin, ti won si fi pari idekun, Islaam wa lati ko awon eniyan ni iwa rere, ki o si fi sagbega fun awon emi, Olohun ti Ola Re so pe:

"الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الإِسْلاَمَ دِينًا فَمَنِ اضْطُرَّ فِي مَخْمَصَةٍ غَيْرَ مُتَجَانِفٍ لإِثْمٍ فَإِنَّ اللّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ" {المائدة/3}

“Lonii ni Mo pa ri esin yin fun yin, Mo si se asepe idera mi fun yin, Mo si yonu si Islaam ni esin fun yin, Nitori naa, enikeni ti inira ebi ba mu (je eran eewo), yato si olufinnufindo – dese, dajudaju Olohun ni Alaforijin, Alaanu”. (Suurah al – Moo’idah: 3)

Oun ni esin ti Olohun yonu si fun omoniyan lati se, kosi ni i gba esin miran to yato si lojo ikeyin, esin kan ni ti o je ipepe si imu – Olohun – lokan, ati a i si imu orogun pelu Olohun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّهُ مَن يُشْرِكْ بِاللّهِ فَقَدْ حَرَّمَ اللّهُ عَلَيهِ الْجَنَّةَ وَمَأْوَاهُ النَّارُ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ" {المائدة/72}

"Dajudaju enikeni ti o ba ba Olohun wa egbera, Olohun ti se Ogba Idera ni eewo fun un, Ina si ni ibugbe re, ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi” (Suurah: al–Moo’idah: 72)

 esin islam pepe si awon Iwa Alaponle awon iwa abiyi, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلْ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَالإِثْمَ وَالْبَغْيَ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَأَن تُشْرِكُواْ بِاللّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا وَأَن تَقُولُواْ عَلَى اللّهِ مَا لاَ تَعْلَمُونَ" {الأعراف/33}

“So pe: ‘Ohun ti Oluwa mi se ni eewo ni awon iwa ibaje – ohun ti o foju han ninu re ati ohun ti o pamo – ati iwa ese ati ote sise lailetoo ati biba Olohun wa egbera – ti ko si so awijare kan kan kale lori re, tabi siso oro nipa Olohun ni nnkan ti eyin ko nimo nipa re” (Suurah al-A‘raaf: 33)

 Esin islam pepe si ise rere ati daadaa sise si awon eniyan. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا ارْكَعُوا وَاسْجُدُوا وَاعْبُدُوا رَبَّكُمْ وَافْعَلُوا الْخَيْرَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ" {الحج/77}

“Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ruku, e fori kanle, e josin fun Oluwa yin, ki e si se rere nitori ki e le jere” (Suurah al – Hajj: 77)

 Islam ni Ipepe gbigbe iwa buburu ati awon iwa egbin ju sile. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَذَرُواْ ظَاهِرَ الإِثْمِ وَبَاطِنَهُ إِنَّ الَّذِينَ يَكْسِبُونَ الإِثْمَ سَيُجْزَوْنَ بِمَا كَانُواْ يَقْتَرِفُونَ" {الأنعام/120}

“Ki e si fi eyi ti o han ninu ese ati eyi ti o pamo ninu re sile, Dajudaju awon ti n se ise ese, Awa yoo san won ni esan ohun ti won n da lese” (Suurah al – Ani’aam: 120)

 Islam ni esin gbogbo eda abara, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنِّي رَسُولُ اللّهِ إِلَيْكُمْ جَمِيعًا الَّذِي لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ لا إِلَهَ إِلاَّ هُوَ يُحْيِي وَيُمِيتُ فَآمِنُواْ بِاللّهِ وَرَسُولِهِ النَّبِيِّ الأُمِّيِّ الَّذِي يُؤْمِنُ بِاللّهِ وَكَلِمَاتِهِ وَاتَّبِعُوهُ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ" {الأعراف/158}

“So pe: ‘Eyin eniyan, dajudaju emi ni Ojise Olohun si gbogbo yin patapata, (Olohun) Eni ti O ni ikapa awon sanmo ati ile, Ko si Olohun ti ijosin to si afi Oun, O n so ni di alaaye, O si n so ni di oku, Nitori naa, e ni igbagbo ododo ninu Olohun ati Ojise Re, anabi alaimoko – mo ka, eni ti o ni igbagbo ododo ninu Olohun ati awon oro Re, E tele e nitori ki e le mona” (Suurah al-A‘raaf: 158)

 islam ike lo je fun gbogbo eda abara, pelu re ni won o fi maa kuro ninu awon okunkun lo si inu imole, pelu re si won o fi maa yo awon eda kuro nibi iya – ina, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلاَّ رَحْمَةً لِّلْعَالَمِينَ" {الأنبياء/107}

“Awa ko si fi ise imisi ran o bi ko se pe ki o le je ike fun gbogbo eda” (Suurah al – Anbiyya: 107

 Islam ni esin ti o fun ni ni ominira to peye, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَقُلِ الْحَقُّ مِن رَّبِّكُمْ فَمَن شَاء فَلْيُؤْمِن وَمَن شَاء فَلْيَكْفُرْ إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلظَّالِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمْ سُرَادِقُهَا وَإِن يَسْتَغِيثُوا يُغَاثُوا بِمَاء كَالْمُهْلِ يَشْوِي الْوُجُوهَ بِئْسَ الشَّرَابُ وَسَاءتْ مُرْتَفَقًا {الكهف/29}

“So pe: “Otito (niyi) lati odo Oluwa yin, Nitori naa, eni ti o ba fe ki o gbagbo ni ododo, Eni ti o ba si fe ki o saigbagbo, Dajudaju A ti pese Ina sile de awon alabosi, ti ogba re yoo yi won po, Ti won ba n bere iranlowo lati mu omi A oo fun won ni omi mimu kan ti o da bi oje ide gbigbona, ti (igbona re) yo si maa bo oju (won), O buru ni mimu, O si buru ni ibukojo.” (Suurah al – Khaf: 29)

 Islam ni Esin ise – sise ati asepe ise, Ojise Olohun (ki Ike ati Ola Olohun maa ba a) so pe: "Olohun ti Ola Re ga nife si ki o je pe ti enikookan yi ba fe se ise ki o se e daadaa lonan to rewa", (Al – bayhkiyy lo gba a wa ninu sha’abul Imaam al – baaniy jeeri si alaaafia hadith yii ninu Sohiih Jaamiu: 1,880 As – Sohiiha: 1, 113).

 Islam ni Esin imo, Ojise Olohun (ki ike ati Ola maa ba a) so pe: "oranyan ni wiwa imo fun gbogbo Musulum" (Ibn Maajah lo gba a wa 2224).

 Islam ni esin imora ati imototo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يَا بَنِي آدَمَ خُذُواْ زِينَتَكُمْ عِندَ كُلِّ مَسْجِدٍ وكُلُواْ وَاشْرَبُواْ وَلاَ تُسْرِفُواْ إِنَّهُ لاَ يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ" {الأعراف/31}

“Eyin omo (Anabi) Aadam, e wo (aso) oso yin ni igbakigba ti e ba n lo si mosalasi, E maa je, ki e si maa mu, ki e si ma se lo ilo apa, Dajudaju (Olohun) ko nifee awon onilokulo.” (Suurah Al – ‘a – raaf: 31)

 Islam ni esin ike ati aanu, Ojise Olohun (ki ike ati Ola maa baa) so pe: "Awon to maa n saanu eniyan Olohun Oba Ajoke Aye naa o maa saanu won ni (nipa bayii) e maa saanu awon eda ori ile aye, awon to wa ninu sanmo naa o maa saanu eyin naa" (Tirimidhiy lo gba a wa, ni Hadith 1924).

 Islam ni esin deede sise laarin gbogbo awon eniyan, Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّ اللّهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالإِحْسَانِ وَإِيتَاء ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاء وَالْمُنكَرِ وَالْبَغْيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ" {النحل/90}

“Dajudaju Olohun n pa ase sise deede, sise rere, ati fifun ebi (ni nnkan), O si n ko agbere sise, iwa aidaa ati tenbelekun, O n se waasi fun yin nitori ki e le lo isiti.”

 (Suurah a-n-Nahl: 90)

 Islam ni esin irorun ati amojukuro, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يُرِيدُ اللّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلاَ يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ وَلِتُكْمِلُواْ الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُواْ اللّهَ عَلَى مَا هَدَاكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ" {البقرة/185}

“Olohun gbero irorun fun yin, ko si fe inira fun yin, E pe onka (ojo aawe), ki e si gbe titobi fun Olohun, nitoir pe O fi ona mo yin ati nitori ki e le maa dupe fun Un”

(Suurah al – baqoorah: 185)

 Islam ni esin ti o daabo bo emi, Olohun ti Ola re ga so pe:

"وَلاَ تَقْتُلُواْ أَنفُسَكُمْ إِنَّ اللّهَ كَانَ بِكُمْ رَحِيمًا" {النساء/29}

“e maa se iku pa emi yin, Dajudaju Olohun n je Alaanu si yin” (Suurah Nisaahi: 29)

 Islam ni esin ti o daabo bo ode ara pelu imora ati imototo, Olohun ti Ola re ga so pe:

"إِنَّ اللّهَ يُحِبُّ التَّوَّابِينَ وَيُحِبُّ الْمُتَطَهِّرِينَ" {البقرة/222}

“Dajudaju Olohun nife awon oluronupiwada, O si nife si awon olumora” (Suurah al-Baqoorah:222)

 Islam ni esin ti o daabo bo inu ara, pelu ainan inan-apa nibi jije ati mimu, aini koja ala eleyii ti o le fa inira, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وكُلُواْ وَاشْرَبُواْ وَلاَ تُسْرِفُواْ إِنَّهُ لاَ يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ" {الأعراف/31}

“E maa je, ki e si maa mu, ki e si ma se lo ilo apa, Dajudaju (Olohun) ko nifee awon onilokulo.” (Suurah Al – ‘a – raaf: 31)

 Islam ni esin ti o daabo bo awujo, Olohun ti ola Re ga sope:

"وَلاَ تُفْسِدُواْ فِي الأَرْضِ بَعْدَ إِصْلاَحِهَا ذَلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ" {الأعراف/85}

“Esi ma se ba ileje leyin atunse re, iyen ni o dara fun yin ti e ba je onigbagbo ododo” (Suurah – Al – AR – Rorf: 85)

Islam ni esin pelepele sise pelu awon eranko ati idaabo bo won, Ojise Olohun (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) so pe: Laarin igba ti okunrin kan nlo, ti o ngbe to lagara n gbe, o ba sokale sibi kanga kan, o mu omi nibe, leyin naa o jade, O ba ri aja kan to yo ahan dinu fun ongbe ti o le, ti o n je erupe nitori ongbe yii. O ba so pe: Iru ibi ti ongbe de lara mi ongbe ti de ibe lara Ajayii naa, o ba bu omi tokun inu bata Khufffi re, leyin naa o fi enu re gbe e, leyin naa ni o gun’ke, o si fun aja naa lomi mu, Olohun si tori re dupe fun un, o si saforijin fun un, Awon Shaabe beere pe, Ojise – Olohun: Se a oo tun maa gbesan latari awon daba bi? O dahun pe: nibi gbgbo daadaa sise si ohun to ni edo tutu ni esan n be lori e, (Itumo ohun to ni edo tutu ni: gbgbo nnkan elemi)

 Islam ni esin deede ati daada, Olohun ti ola Re ga sope:

"إِنَّ اللّهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالإِحْسَانِ وَإِيتَاء ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاء وَالْمُنكَرِ وَالْبَغْيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ" {النحل/90}

“Dajudaju Olohun n pa ase sise deede, sise rere, ati fifun ebi (ni nnkan) O si n ko agbere sise, iwa aidaa ati tenbelekun, O n se waasi fun yin nitori ki e le lo isiti.”

 (Suurah a-n-Nahl: 90)

 Islam ni esin deede laarin gbogbo eda, Ojise – Olohun (ki ike ati Ola maa ba a) so pe: "Eyin eniyan, okansoso ni Olohun yin, Okansoso ni Baba yin e gbo mi, kosi ajulo fun Larubawa lori awon Elede miiran, bakan naa kosi fun elede miiran lori Laburawa kosi fun Alawo – dudu lori Alawo – pupa, kosi si fun Alawo pupa lori Alawo – dudu naa, ayafi pelu iberu Olohun". (Imam Ahmad lo gba a wa. Hadith 23536).

 Sugbon isesi eda Abara nile – aye nipe Olohun maa n gbe apa kan ga ju apa kan lo ninu Arisiki won ati eto isemi won, O maa n se awon kan ni Oloro, awon kan ni Alaini ninu won. Gege bi Olohun ti Ola Re ga se so pe:

"وَاللهُ فَضَّلَ بَعْضَكُمْ عَلَى بَعْضٍ فِي الْرِّزْقِ فَمَا الَّذِينَ فُضِّلُواْ بِرَآدِّي رِزْقِهِمْ عَلَى مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَهُمْ فِيهِ سَوَاء أَفَبِنِعْمَةِ اللّهِ يَجْحَدُونَ" {النحل/71}

“Olohun lo se ajulo fun apa kan yin lori apa kan ninu arisiki, Awon ti A fun ni ajulo won o le fun awon ti n be ni ikapa won ni arisiki won, ti won o fi wa se deede ni ibe, se idera Olohun ni won yoo maa tako?” (Suurah a-n-Nahl: 71)

 A maa se awon miiran ni Alaisan, awon miran ni Eni toni Alaafia, awon miran ni eni giga, awon miran ni eni kukuru, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"نَحْنُ قَسَمْنَا بَيْنَهُم مَّعِيشَتَهُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَرَفَعْنَا بَعْضَهُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ لِيَتَّخِذَ بَعْضُهُم بَعْضًا سُخْرِيًّا وَرَحْمَتُ رَبِّكَ خَيْرٌ مِّمَّا يَجْمَعُونَ" {الزخرف/32}

 “Awa ni A pin ohun isemi won fun won ninu igbesi aye, A si fi awon ipo gbe apa kan won ga ju apa kan lo, nitori ki apa kan won le maa sise fun apa kan, Ike Oluwa re dara ju ohun ti won n ko jo lo” (Suurah a-z-Zukruf: 32)

 Olohun se awon kan ni Agan, awon kan si je eni ti n ri omo bi, Olohun naa lo tun pin iru iran omo ti o ma waye laarin awon eda re, ako tabi abo, dida ako atabo po, nipa bayi, Olohun maa n da ohun to ba wu, O si maa n se ohun to ba wu, nitori ogbon kan to se pe enikan kan o da mo ayafi OUN naa, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"لِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ يَخْلُقُ مَا يَشَاء يَهَبُ لِمَنْ يَشَاء إِنَاثًا وَيَهَبُ لِمَن يَشَاء الذُّكُورَ * أَوْ يُزَوِّجُهُمْ ذُكْرَانًا وَإِنَاثًا وَيَجْعَلُ مَن يَشَاء عَقِيمًا إِنَّهُ عَلِيمٌ قَدِيرٌ" {الشورى 49/50}

“Ti Olohun ni Ijoba awon sanmo ati ile, O n seda ohun ti O ba fe, O n ta eni ti O ba fe ni ore omobinrin, O si n ta eni ti O ba fe ni ore omokunrin * Tabi ki O se won ni orisi meji; ako ati abo, O si n se eni ti O ba fe ni agan, Dajudaju Oun ni Olumo, Alagbara” (Suurah: 49 – 50)

 E lo mo wipe gbogbo oju onan esin ati gbogbo esin miran -yato si esin Islaam ti o je ipepe Anabi ikeyin ti i se Muhammad (ki ike at Ola Olohun maa ba a)- ni won kun lowo ni onan ti o han tabi ni onan ti o han, ni ikunlowo ti koni enu ala, lati odo awon elesin agbaye (sohayuun ) eyi ti o ri pe ewu wa fun oun nibi lilo eto Ilsam ti o je esin alaafia, Bakan naa wiwo danu tun le sele si erongba oun, nibi mimu awon eiyan sin ati jijegaba lori awon oore ile aye yi, gege bi o se n gbiyanju pelu gbogbo agbara ti won fun un lori idasile awon oju ona ijosin ati awon ijo ijo tuntun, latari ifowosowope, ajosepo ati imu are eni lore, ati titakete si gbogbo ipile kan ti omoniyan to je omoluabi kole yonu si, won n se Gbogbo eleyi fun iberu isokan omoniyan labe esin ododo, eyi ti o se pe pelu hihan re ni ododo o se foju han, ti iro o si pare, ti olugbagbo ododo si le mori bo lowo awon ti o fe yepere re, ti won fe mu un sin, ti won fe gba awon oore ilu re, Bakan naa ti won si fe ko yipada lati ibi imaa sin Olohun Oba Adedaa lo sibi imaa sin eda.

 

 

ISERI PADA SI IPILE

Kosi iyemeji nibi wi pe asiko tito bayi fun gbogbo enikookan wa kio pada sibi ipile esin re, ti o se pe Olohun ti o mo julo ti Ola Re ga julo yonu si, ti i se Islaam, asiko yii lo si dara to ba rorun bayi, tori pe o le ma rorun mo lasiko miran, tori pe ti o ba ri aye re loni, O le ma ri aye re lola, koda ko se pe eniyan fe bee. Olohun so pe:

"وَلَيْسَتِ التَّوْبَةُ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ حَتَّى إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ إِنِّي تُبْتُ الآنَ وَلاَ الَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمْ كُفَّارٌ أُوْلَئِكَ أَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا" {النساء/18}

“Ko si ironupiwada fun awon ti n se aburu titi iku fi de ba okan ninu won, ki o wi pe: Dajudaju emi ronu piwada nisinsin yii, kosi si fun awon ti won ku sipo aigbagbo, Awon wonyi, A ti pese iya elete elero sile de won” (Suurah a-n-Nisaa: 18)

 Gege bi Olohun ti Ola Re ga se salaye isesi keferi lasiko ipoka – iku nigba ti o ri iku, to si ripe awon ododo ti foju han si oun kedere, ti o ti mo ododo oro awon Ojise Olohun, to si ti ri ibaje esin eyi ti o wa lori re, ti o wa n sabamo lori ohun ti o fi se atetere, bee si ni kosi aye fun abamo sise lasiko yen mo, ni iru isesi bayii, won ti ti ilekun gbigba ironupiwada fun eru, bakan naa si ni won ti tilekun ipada saye, yoo maa wa banuje, yoo si maa rankan a ti pada saye kofi le wa gba ohun ti o saigbagbo re, Sugbon oro ti amuse re jinna tefe ni eyi, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"حَتَّى إِذَا جَاء أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ رَبِّ ارْجِعُونِ * لَعَلِّي أَعْمَلُ صَالِحًا فِيمَا تَرَكْتُ كَلاَّ إِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَائِلُهَا وَمِن وَرَائِهِم بَرْزَخٌ إِلَى يَوْمِ يُبْعَثُونَ" {المؤمنون 99/100}

“titi di igba ti iku fi de ba okan ninu won, O si wipe: “Oluwa mi, E da mi pada (sile aye). * nitori ki emi le se ise rere ninu eyi ti mo gbe ju sile, Ko ri bee rara, dajudaju o je oro kan ti o kan n wi ni, (amo) gaga ti wa ni eyin won titi di ojo ti A oo gbe won dide” (Suurah Al – Mu’miinuun: 99 – 100)

 Al – Qur’aan ti gbe eyi wa fun wa ninu itan Fir’aona eni ti o koja ala Olohun ti o so pe: Emi ni Olohun yin ti o ga julo, nigba ti o foju ri ododo ni riri oju, o gba Olohun gbo sugbon igbagbo re yi kose lanfaani mo, tori naa, Olohun te oun ati awon omo-ogun re sinu omi, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَائِيلَ الْبَحْرَ فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ وَجُنُودُهُ بَغْيًا وَعَدْوًا حَتَّى إِذَا أَدْرَكَهُ الْغَرَقُ قَالَ آمَنتُ أَنَّهُ لا إِلِهَ إِلاَّ الَّذِي آمَنَتْ بِهِ بَنُو إِسْرَائِيلَ وَأَنَاْ مِنَ الْمُسْلِمِينَ * آلآنَ وَقَدْ عَصَيْتَ قَبْلُ وَكُنتَ مِنَ الْمُفْسِدِينَ * فَالْيَوْمَ نُنَجِّيكَ بِبَدَنِكَ لِتَكُونَ لِمَنْ خَلْفَكَ آيَةً وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ النَّاسِ عَنْ آيَاتِنَا لَغَافِلُونَ" {يونس 90/92}

“A mu awon omo Isroo’iil la agbami okun ja, Fir’aon ati awon omo ogun re si gba to won leyin, ni ti abosi ati itayo enu – aala, titi iteri sinu agbami okun fi ba a, o si wi pe: “mo gbagbo pe dajudaju ko si Olohun ti ijosi to si afi eni ti awon omo Isroo’iil gbagbo, Mo si wa ninu awon musulumi. * Se nisin yii, ti iwo ti yapa siwaju, ti o si wa niu awon obileje? * Nitori naa, ni oni ni A o gbe oku re jade si ori ile tente, nitori ki o le je ami (feyikogbon) fun awon ti n bo leyin re, Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma n fonu – fora nipa awon aami Wa.” (Suurah Yuunus: 90 – 92)

 Akole yi je elege, bakan naa o je ohun to leto ki Arojinle waye lori re, oro naa Oriire gbere ni, ti oriburuku ki gbeyin re, ninu Alujannah eleyi ti ebu re fe se deede awon sanmo ati ile, tabi oriburuku gbere ti oriire ki i gbeyin re, ninu Ina Jahanamoh, eleyi ti o je ibudesi ‘bu, Olohu ti Ola Re ga so pe:

"لَهُم مِّن جَهَنَّمَ مِهَادٌ وَمِن فَوْقِهِمْ غَوَاشٍ وَكَذَلِكَ نَجْزِي الظَّالِمِينَ" {الأعراف/41}

“Ite wa fun won ninu ina Jaanamo, Orule si wa fun won ni oke won, Bayen ni A se n san awon alabosi ni esan” (Suurah Al –‘a’raaf: 41)

 Olohun ti o da e, maa n dunnu si (tutuba) ironpiwada re ati iseri pada re sode Re, enmo bi O se tobi to ni Adeda, O gbero daada ro wa, gege bi ojise Olohun (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) se royin re fun wa pelu oro re pe: "Olohun maa n dunnu gan pelu ironupiwada eru re nigba ti o ba ronu piwada losi odo Re, ju enikan ti o n be ni ori nkan-gun re ni ile papa, ti nkan-gun yi wa bo mo lowo, onje re ati omi re si wa lori nkan-gun naa, ni o ba lo si abe igi kan, ti o si sun si abe iboji re leni ti o ti jakan kuro ni ara nkan-gun naa, laarin igba ti o wa be, ni nkan naa ba de si iwaju re, ni oba gba ijanu re mun, leyin naa ni o wa wipe: ( iwo ni eru mi, emi ni Oluwa re) o siso fun idunu ti o ni agbara" (muslim)

 Enmo bi aanu Oba Adeda se to, O gbero lati se ike wa, O si gbero orire wa, gege bi ojise Olohun se royin (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) ninu oro re pe: "dajudaju, ogorun – un ike lo wa fun Olohun, O so eyokan kale laarin awon eniyan, Alujannu, awon eran – osin, ati awon erankoo miran, pelu ike kan yii ni won fi n saanu ara won, ti won si fi n ke ara won, ike kan yii naa ni iya fi n saanu omo re, Olohun wa fi mokandinlogorun ike yoku pamo lati fi ke awon erusin Re lojo igbende” (Sohihi Muslim).

 Ka awon Ayat Al – Qur’aan yii ki o fi le mo esan nla ti o wa lodo Olohun Oba Adeda re, nibi pipada re si ipile esin re ti se Islaam ati Igbagbo si awon ofin esin to sokale keyin, ati esan ti o maa ri pelu ipada re sodo Re, yi O se aforijin gbogbo ese re ti yi O si se ayipada gbogbo aida si daadaa. Nje o gbo iru aponle bayi ri? Olohun ti Ola ga so pe:

"وَالَّذِينَ لاَ يَدْعُونَ مَعَ اللَّهِ إِلَهًا آخَرَ وَلاَ يَقْتُلُونَ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللَّهُ إِلاَّ بِالْحَقِّ وَلاَ يَزْنُونَ وَمَن يَفْعَلْ ذَلِكَ يَلْقَ أَثَامًا * يُضَاعَفْ لَهُ الْعَذَابُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَيَخْلُدْ فِيهِ مُهَانًا *إِلاَّ مَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ عَمَلاً صَالِحًا فَأُوْلَئِكَ يُبَدِّلُ اللَّهُ سَيِّئَاتِهِمْ حَسَنَاتٍ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا * وَمَن تَابَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَإِنَّهُ يَتُوبُ إِلَى اللَّهِ مَتَابًا" {الفرقان 68/71}

“(Awon ni) awon ti won ki i pe olohun miran mo Olohun, Won ki i pa emi ti Olohun se (pipa re) ni eewo afi pelu eto, Ati pe won ki i se sina, Enikeni ti o ba se (aburu) yen, o ma pade (iya) ese (re)* A oo se iya ni ilopo fun un ni Ojo Ajinde, O si maa se gbere ninu re ni eni yepere * Afi eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere taara, Awon wonyen ni Olohun yoo fi ise rere ropo ise aburu won, (iyen nipa ironupiwada won), Olohun si n je Alaforijin, Onikee* Enikeni ti o ba ronu piwada, ti o si se ise rere, (ki o mo) pe dajudaju oun ronu piwada patapata si odo Olohun ni. ” (Suurah al – Furqoon: 68 – 71)

 Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قُل لِلَّذِينَ كَفَرُواْ إِن يَنتَهُواْ يُغَفَرْ لَهُم مَّا قَدْ سَلَفَ وَإِنْ يَعُودُواْ فَقَدْ مَضَتْ سُنَّةُ الأَوَّلِينِ" {الأنفال/38}

“So fun awon ti won saigbagbo pe ti won ba jawo (nibi aigbagbo), A maa se aforijin ohun ti o ti re koja fun won, Ti won ba si tun pada (sibe, apejuwe) iparun awon eni akoko kuku ti re koja (ni ikiko fun won). (Suurah Al – anfaal: 38)

 Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَالَّذِينَ إِذَا فَعَلُواْ فَاحِشَةً أَوْ ظَلَمُواْ أَنْفُسَهُمْ ذَكَرُواْ اللّهَ فَاسْتَغْفَرُواْ لِذُنُوبِهِمْ وَمَن يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلاَّ اللّهُ وَلَمْ يُصِرُّواْ عَلَى مَا فَعَلُواْ وَهُمْ يَعْلَمُونَ" {آل عمران/135}

“Awon ti (o je pe) nigba ti won ba se aida kan tabi won se abosi si ori ara won, won a ranti Olohun, won a si toro aforijin fun ese won, Tani eni ti n fori awon ese jin (eda) bi ko se Olohun, Won ko si ni taku si ori ohun ti won n se nigba ti won mo (pe ese ni)". (Suurah aali – Imroon: 135)

 Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّمَا التَّوْبَةُ عَلَى اللّهِ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السُّوَءَ بِجَهَالَةٍ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِن قَرِيبٍ فَأُوْلَئِكَ يَتُوبُ اللّهُ عَلَيْهِمْ وَكَانَ اللّهُ عَلِيماً حَكِيماً" {النساء/17}

“dajudaju, ironupiwada ti Olohun yoo gba ni ti awon ti n se ise aburu pelu aimokan, Leyin naa, won ronu piwada laipe (iyen siwaju ipokaka iku), Awon wonyi ni Olohun yoo gba ironupiwada won, Olohun si je Olumo, Ologbon” (Suurah a-n-Nisaa: 17)

 Olohun ti Ola Re ga so pe:

" وَاللَّهُ يُرِيدُ أَنْ يَتُوبَ عَلَيْكُمْ وَيُرِيدُ الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ الشَّهَوَاتِ أَنْ تَمِيلُوا مَيْلًا عَظِيمًا (27)" (النساء:27)

"Olohun fe fi orojin yin, awon ti won ntele ojukokoro si fe ki e gunri kuro ni onan tefetefe"(an-nisai:27)

Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ لِّلنَّاسِ عَلَى ظُلْمِهِمْ وَإِنَّ رَبَّكَ لَشَدِيدُ الْعِقَابِ {الرعد/6}

“dajudaju Oluwa re ni Alaforijin fun awon eniyan lori abosi (owo) won, Dajudaju Oluwa re le nibi iya". (Suurah a-r-Ra’d: 6)

 Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَإِنِّي لَغَفَّارٌ لِّمَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا ثُمَّ اهْتَدَى" {طه/82}

“Dajudaju Emi ni Alaforijin fun enikeni ti o ba ronu piwada, ti o si gbagbo ni ododo, ti o tun se ise rere, leyin naa ti o tun tele imona” (Suurah Toohaa: 82)

 Olohun ti Ola Re ga so pe:

" وَلَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ فِيمَا أَخْطَأْتُم بِهِ وَلَكِن مَّا تَعَمَّدَتْ قُلُوبُكُمْ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا" {الأحزاب/5}

“Ko si ese fun yin nipa ohun ti e ba fi se asise, sugbon (ese wa nibi) ohun ti okan yin moomo se, Olohun si je Alaforijin, Alaaanu” (Suurah a-s-Sajdah: 5)

 Eni ti ko ba ri ola nla yii, a je pe Olusatete re ni, Olohun tola Re ga so pe:

"إِن تُبْدُواْ خَيْرًا أَوْ تُخْفُوهُ أَوْ تَعْفُواْ عَن سُوَءٍ فَإِنَّ اللّهَ كَانَ عَفُوًّا قَدِيرًا" {النساء/149}

“Ti eyin ba se oore kan ni gbangban, tabi e se e ni bonkele, tabi e se amojukuro nibi iwa aidara kan, dajudaju Olohun je Alamojuukuro, Alagbara” (Suurah a-n - Nisaa: 149)

 Olohun ti o gbon – ngbon ti Ola Re si ga julo wi bayii pe: "Ire Omo Adam! Dajudaju, ti o ba ti le maa pe Mi, ti o si ni ireti (oore lati odo) Mi, n O se aforijin fun o nipa nnkan yowu ti o ba n be lodo re (ninu ese) N ko si ni bikita, ire omo Adam, ti o ba se pe ese re ba po ti o fe kan kurukuru sanmo, leyin naa ti o waa toro aforijin lodo Mi, n O se aforijin fun o, ire omo Adam. Dajudaju, ti o ba se pe iwo de wa ba Mi pelu awon ese ti o bo gbogbo ori – ile aye, ti o si de odo Mi, lai pa nnkan miiran po mo ijosin Mi, n O pade re pelu aforijin ti o tobi ju u (ile) lo, (Ahmad ati Tirimidhi lo gba a wa. Al – Albaaniy jeri pe o ni alaafia. 127)

 Ojise Olohun (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) sope: "Emi mo eni ti yoo wo Alujannah gbeyin, ati eni ti yoo jade ninu ina keyin, oun ni okunrin kan ti won o mu wa lojo igbende, ti won o so pe: E fi awon ese re kekeke han an, ki e si gbe awon ese re nla nla kuro lodo re, won o ba fi awon ese re kekeke han an, won o si so pe: o se nnkan bayi, bayi, bayi, bayi, yoo si dahun pe beeni koni lagbara a ti le se atako, yoo ba di eni ti n wa aanu lori awon ese re nlanla pe ki won ma fi le seri re si oun, Won yoo ba so fun pe: Daadaa n be fun paro gbogbo aida kookan, Yoo ba dahun pe: Olohun Olutoju – eda, mo ti se opolopo nnkan ti mi o ri i nibi yii” Eni ti o gba a wa ni mo ri Ojise – Olohun (ki ike ati Ola Olohun maa ba a) ti o rerin titi ti awon eyiin ogan re fi han sita". (Muslim lo gba a wa).

 

 

AWON ASIKO FUN AROJINLE

            Gbogbo awon esin ti n be lori ile ninu iwoye Islaam lo je ohun ibaje, idi si ni pe mimu nnkan miran mo Olohun maa n wa nibe, ati imaa sin eni ti o yato si Olohun mo Olohun, tabi ki a pe tori won je awon esin ti ko wa lati sanmo, eda abara lo da a sile lati gbo bukata adamo to wa fun won, ati lati ri esin ti won o maa sin, sugbon won o fi won se konge ododo ati ona ti o to, tori pe kosi esin miran mo leyin Islaam, Ki o si file mo pe awon iwe ofin esin to wa lati sanmo (ti a le ri bayi) awon naa ni t – taorah, Al – Injil ati Al – Qur’aan ti i se iwe ofin Muhammad (ki ike ati Ola maa ba a) o je edun okan pe ojulowo At – taorah ati Al – Injil kosi mo bi ko se pe Agbelero ti awon eniyan ti kowo bo ojulowo re ni a le ri, eleyii si n tokasi pe itakorawon ti o foju han ni o ti wa nibe, imu orogun mo Olohun ati oro abuku si Olohun ti Ola Re ga lo wa ninu awon tira Agbelero wonyi , Gbogbo alaye eyi ti wa ninu awon tira adase kan, fun eni ti O ba fe ri ni ifosiwewe, ohunkan ti won fe ki gbogbo eni ti O ba ka a, o se, nipe ki O seri esin re sinu opolo, ki o si beere, wi pe: Nje eleyii ba opolo mu bi, ki a maa sin awon olohun kan, ti won ko le lagbara ati le sanfaani fun ara won, tabi se inira kan fun ara won? Nje O ba opoloo mu ki a maa safomo fun eda bii ti wa, ti ko kappa lati mu iku, iye, tabi Akojo awon eda wa? Nje O ba opolo mu ki a roro pelu eda dipo Oba Adeda, ti O si je pe eda yii ko lagbara lati ka inira kuro fun wa tabi ki o se ayipada inira? Nje o ba opolo mu ki a maa sin eda Abara bii ti wa, ti ko le da nnkan kan, bi ko se pe won da oun naa ni?

 Ijosin ninu Islaam ni ododo, ohun ti o je ti Olohun Adedaa nikansoso, ti eda kan ko ni ipin ninu e. A pe eni ti O n tele oju – kokoro ati ifenu re, ohun to je (Halaal) eto ni ohun ti Olohun fe, ohun ti O si je (Haroom) eewo ni ohun ti Olohun korira, Nipa bayii, ronu si oro Olohun ti Ola Re ga yi, Olohun ti Ola Re ga so bayi pe:

"وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ" {غافر/60}

“Oluwa yin so pe: E pe mi, ki njepe yin, Dajudaju awon eni ti n se igberaga si jijosi funMI, Won o wo inu ina jaanamo ni eni yepere” (Suuroh Goofir: 60)

 Ijosin ninu Islaam ni ohun ti o waye laarin Olohun ati awon eru re lai ni awon Alagata ati Olusipe, Olohun Oba ti Ola Re ga so pe:

"أَلاَ لِلَّهِ الدِّينُ الْخَالِصُ وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِهِ أَوْلِيَاء مَا نَعْبُدُهُمْ إِلاَّ لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللَّهِ زُلْفَى إِنَّ اللَّهَ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ فِي مَا هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ إِنَّ اللَّهَ لاَ يَهْدِي مَنْ هُوَ كَاذِبٌ كَفَّارٌ" {الزمر/3}

“e gbo o! Ti Olohun ni esin mimo, Awon ti won si mu awon alafeyinti kan yato si Olohun (won wi pe): Awa ko josin fun won bi ko se pe nitori ki won le mu wa sunmo Olohun pekipeki ni.” Dajudaju Olohun maa dajo laarin won nipa ohun ti won n yapa enu nipa re (iyen, esin ‘Islaam), Dajudaju Olohun ko ni fi ona mo eni ti o je opuro, alaigbagbo” (Suurah a-z-Zumor: 3)

 

 

AWON AAYAH TI O SO NIPA AROJINLE FUN ENI TI O MU NKAN MIRAN MO OLOHUN NINU IJOSIN

 Nipa alaye abuku to wa fun gbogbo nkan miran ti won sin yato si Olohun ni gbogbo onan, ninu re ni Oro Olohun Oba to gbon – ngbon, ti Ola Re ga ti o sope:

"وَاتَّخَذُوا مِن دُونِهِ آلِهَةً لاَّ يَخْلُقُونَ شَيْئًا وَهُمْ يُخْلَقُونَ وَلاَ يَمْلِكُونَ لإِنفُسِهِمْ ضَرًّا وَلاَ نَفْعًا وَلاَ يَمْلِكُونَ مَوْتًا وَلاَ حَيَاةً وَلاَ نُشُورًا" {الفرقان/3}

“(Awon alaigbagbo) si n josin fun awon orisa kan leyin Olohun, Won ko si le da kini kan, A si da won ni. won ko si ni ikapa inira tabi anfani kan fun emi ara won, Ati pe won ko ni ikapa lori iku, isemi ati ajinde” (Suurah: al - Furqoon: 3)

 Nipa kigakara gbogbo nkan ti won sin leyin Re (Olohun), Oro Olohun ti o gbongbon ti Ola Re ga sope:

"قُلْ أَفَرَأَيْتُم مَّا تَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ إِنْ أَرَادَنِيَ اللَّهُ بِضُرٍّ هَلْ هُنَّ كَاشِفَاتُ ضُرِّهِ أَوْ أَرَادَنِي بِرَحْمَةٍ هَلْ هُنَّ مُمْسِكَاتُ رَحْمَتِهِ قُلْ حَسْبِيَ اللَّهُ عَلَيْهِ يَتَوَكَّلُ الْمُتَوَكِّلُونَ" {الزمر/38}

"So pe: “E so fun mi nigba naa awon nnkan ti eyin n pe leyin Olohun, ti Olohun ba gbero inira kan ro mi, nje won le mu inira Re kuro fun mi? Tabi ti O ba gbero ike kan fun mi, nje won le mu ike Re duro bi?” So pe: “Olohun to fun mi, Oun si ni awon ti won ni agbekele n gbara le” (Suurah a-z-Zumor: 38)

 Nipa imu lota ti awon Olusin nnkan miiran leyin Olohun maa mu awon nkan ti won sin lota ni ojo Igbende. Oro Olohun Oba to gbongbon so pe:

"وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّن يَدْعُو مِن دُونِ اللَّهِ مَن لاَّ يَسْتَجِيبُ لَهُ إِلَى يَومِ الْقِيَامَةِ وَهُمْ عَن دُعَائِهِمْ غَافِلُونَ * وَإِذَا حُشِرَ النَّاسُ كَانُوا لَهُمْ أَعْدَاء وَكَانُوا بِعِبَادَتِهِمْ كَافِرِينَ" {الأحقاف 5/6}

“Ta ni o tun sina to tayo eni ti n ke pe eni ti ko le je ipe re leyin Olohun titi di Ojo Ajinde, Atipe won ko ni oye si pipe ti won n ke pe won, * Nigba ti A ba si ko awon eniyan jo (fun Ajinde, awon orisa) yoo di ota fun (awon aborisa) Won si maa tako jijosin ti won n josin fun won” (Suurah al – Ahqoof:5- 6)

 A pe eyin ti e n sin ina, igi, okuta, maalu ati bebelo, E ronu si oro Olohun ti Ola Re ga yii:

"إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ عِبَادٌ أَمْثَالُكُمْ فَادْعُوهُمْ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ * أَلَهُمْ أَرْجُلٌ يَمْشُونَ بِهَا أَمْ لَهُمْ أَيْدٍ يَبْطِشُونَ بِهَا أَمْ لَهُمْ أَعْيُنٌ يُبْصِرُونَ بِهَا أَمْ لَهُمْ آذَانٌ يَسْمَعُونَ بِهَا قُلِ ادْعُواْ شُرَكَاءكُمْ ثُمَّ كِيدُونِ فَلاَ تُنظِرُونِ * إِنَّ وَلِيِّيَ اللّهُ الَّذِي نَزَّلَ الْكِتَابَ وَهُوَ يَتَوَلَّى الصَّالِحِينَ" {الأعراف 194/196}

“Dajudaju awon ti e n pe leyin Olohun eru bi eyin naa ni won, Nitori naa, e pe won wo, ki won da yin lohun ti e ba je olooto * Se won ni ese ti won le fi rin ni? Tabi se won ni oju ti won le fi riran? Abi se won ni eti to won le fi gboro? So pe: “E pe awon orisa yin, leyin naa ki e dete si mi, ki e si ma se lo mi lara. * Dajudaju Alatileyin mi ni Olohun, Eni ti O so Tira naa kale, Ati pe Oun ni n se atileyin fun awon eni reree” (Suurah Al – a’raaf: 194 – 196)

 A pe iwo ti o n rokirika saare, ti o n pe oku, ti o tun n sin awon oku inu saare, ronu si oro Olohun ti Ola Re ga yii:

"وَلاَ تَدْعُ مِن دُونِ اللّهِ مَا لاَ يَنفَعُكَ وَلاَ يَضُرُّكَ فَإِن فَعَلْتَ فَإِنَّكَ إِذًا مِّنَ الظَّالِمِينَ" {يونس/106}

“(maa se pe leyin Olohun nkna ti ko le se o ni anfaani, ti ko si le ko inira ba o, ti iwo ba se bee nigba naa, dajudaju iwo ti wa ninu awon alabosi” (Suurah Yuunus: 106)

 A pe eni ti o n tele oju – kokoro ati ife’nu re, ohun to je (Halaal) eto ni ohun ti Olohun fe, ohun ti o si je (Haroom) eewo ni ohun ti Olohun korira, Nipa bayii, ronu si oro Olohun ti Ola Re ga yii:

"فَإِن لَّمْ يَسْتَجِيبُوا لَكَ فَاعْلَمْ أَنَّمَا يَتَّبِعُونَ أَهْوَاءهُمْ وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنِ اتَّبَعَ هَوَاهُ بِغَيْرِ هُدًى مِّنَ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ لاَ يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ" {القصص/50}

“Ti won ko ba je ipe re, mo pe dajudaju won n tele ife – inu won ni, ko si si eni kan ti o sina to tayo si eni ti o tele life – inu re laisi imona kan (fun) lati odo Olohun, Dajudaju Olohun ko nii fi ona mo ijo alabosi” (Suurah al - Qosos: 50)

 Lo mo pe gbogbo ohunkan ti awon eniyan n sin ni yio mowo mose kuro lodo awon to n sin won, ti won mu won ni olugbowo leyin Olohun, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمِنَ النَّاسِ مَن يَتَّخِذُ مِن دُونِ اللّهِ أَندَاداً يُحِبُّونَهُمْ كَحُبِّ اللّهِ وَالَّذِينَ آمَنُواْ أَشَدُّ حُبًّا لِّلّهِ وَلَوْ يَرَى الَّذِينَ ظَلَمُواْ إِذْ يَرَوْنَ الْعَذَابَ أَنَّ الْقُوَّةَ لِلّهِ جَمِيعاً وَأَنَّ اللّهَ شَدِيدُ الْعَذَابِ * إِذْ تَبَرَّأَ الَّذِينَ اتُّبِعُواْ مِنَ الَّذِينَ اتَّبَعُواْ وَرَأَوُاْ الْعَذَابَ وَتَقَطَّعَتْ بِهِمُ الأَسْبَابُ" {البقرة 165/166}

“O si n be ninu awon eniyan, eni ti n josin fun awon orisa leyin Olohun, Won n nife won gege bi ife (ti o ye ki won ni si) Olohun, Awon ti won gbagbo ni ododo si ni ife ju lo si Olohun., Ti o ba je pe awon ti won se abosi le ri igba ti won maa ri iya naa ni, (won iba mo pe) dajudaju gbogbo agbara n je ti Olohun, Ati pe dajudaju Olohun le (nibi) iya. * (Ranti) nigba ti awon ti won tele (ninu aigbagbo) ti won o yowo yose kuro ninu oro awon ti won tele won, ti won si ri iya, ohun to si so won po yio si ja” (Suurah: al – Baqoorah: 165 – 166)

 Olohun Olutoju wa ti gbe itan Anabi Ibrohiim (ki alaafia Olohun maa ba a) ati Namrudhu olukoja ala, eni ti O pe awon iroyin esa kan to ye Olohun mo ara re, Namruudh pe mo ara re wi pe: oun ni Olukapa lori jiji oku dide, Anabi Ibrohiim (ki Alaafia Olohun maa ba a) O ba jiyan, o si bafi oro jomitoro oro pelu opolo, ki o fi le salaye iro re ati ero ibaje re, nipa bayii O ni ki o se ise miran ti O je ise Olohun ti o ga ti o gbongbon yato si jiji oku, O ni ki o se lara ise ti Olohun maa n se fun eda re laye yii, bii ki o mu oorun wa ni ibuwo re dipo ibuyo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِي حَآجَّ إِبْرَاهِيمَ فِي رِبِّهِ أَنْ آتَاهُ اللّهُ الْمُلْكَ إِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّيَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا أُحْيِي وَأُمِيتُ قَالَ إِبْرَاهِيمُ فَإِنَّ اللّهَ يَأْتِي بِالشَّمْسِ مِنَ الْمَشْرِقِ فَأْتِ بِهَا مِنَ الْمَغْرِبِ فَبُهِتَ الَّذِي كَفَرَ وَاللّهُ لاَ يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ" {البقرة/258}

“Se iwo ko woye si eni ti o ba (Anabi) Ibrohiim jiyan nipa Oluwa re, nitori pe Olohun fun un ni ijoba? Nigba ti (Anabi) Ibroohiim so pe: “Oluwa mi ni Eni ti n so ni di alaaye, O si n so ni di oku, “O wi pe: “Emi naa n so ni di alaaye, Mo si n so ni di oku”. (Anabi) Ibroohim so pe: “O daa, dajudaju Olohun n mu oorun wa lati ibuyo, Mu un wa nigba naa lati ibuwo” “Idaamu opolo ba de ba eyi ti o saigbagbo, (ko si ri oro so mo), Olohun ko si nii fi ona mo ijo alabosi” (Suurah al – Baqoraah: 258)

 Olohun ti Ola Re ga tun so itan Anabi Musa (ki Alaafia Olohun maa ba a) ati Firiaona naa, nigba ti oun naa pe ije Olohun mo ara re, ti Anabi Musa (ki Alaafia maa ba a) si ba jiyan lonan ti o ba opolo mu, lati le salaye iro re ati ikagara re niwaju awon ti o n fi iroyin yi tu je, nipa wi pe, Anabi Musa (ki Alaafia Olohun maa ba a) so pe ki o mu awon irawo jade lati ibuwo – oorun dipo ibuyo re ti won ti n jade tele. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"قَالَ فِرْعَوْنُ وَمَا رَبُّ الْعَالَمِينَ * قَالَ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا إن كُنتُم مُّوقِنِينَ * قَالَ لِمَنْ حَوْلَهُ أَلاَ تَسْتَمِعُونَ * قَالَ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الأَوَّلِينَ * قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ الَّذِي أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ * قَالَ رَبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَا إِن كُنتُمْ تَعْقِلُونَ" {الشعراء 23/28}

“Fir’anon wi pe: “Ki ni Oluwa gbogbo eda?” * (Anabi Musa) so pe: “(Olohun ni) Oluwa awon sanmo, ile ati gbogbo nkan ti n be laaarin awon mejeeji, ti eyin ba je alamodaju” * (Fir’aon) wi fun awon ti won wa ni ayika re pe: “Se eyin ko gbo oro (ti n so ni)? * (Anabi Muusaa) so pe: “(Olohun ni) Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko. * (Fir’aon) wi pe: Dajudaju Ojise yin eyi ti won ran si yin were maa ni. * (Anabi Musa) so pe: “(Olohun ni) Oluwa ibuyo oorun, ibuwo oorun ati ohunkohun tii n be laaarin awon mejeejil tie yin ba je eni ti n se laakaye.” (Suurah a-s-Su’aroo: 23 – 28)

Eleyii maa je ki O mo wi pe eni ti o leto si ijosin ati mimo kuro nibi orogun ni Olohun Oba Okansoso nikan, lo adamo re, ki O si ba laakaye re da imoran, eyi ti o le je ki o mo pe eda lo ni iyepere, ko si iyemeji nibi wi pe yio gbe e lo sibi pe ibaje ni imaa sin awon eda Olohun ati imaa wa won ni olugbowo dipo Olohun.

 

 

 

KI OJO TO LO

            E je ki a fi opolo wa eyi to ni alaafia ronu, ati adamo wa to ni alaafia ronu si ipo ti a wa, tori pe isemi kekere ju pe ki omoniyan lo lori ohun ti koni se lanfaani lo, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"اعْلَمُوا أَنَّمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ وَزِينَةٌ وَتَفَاخُرٌ بَيْنَكُمْ وَتَكَاثُرٌ فِي الأَمْوَالِ وَالأَوْلاَدِ كَمَثَلِ غَيْثٍ أَعْجَبَ الْكُفَّارَ نَبَاتُهُ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَاهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَكُونُ حُطَامًا وَفِي الآخِرَةِ عَذَابٌ شَدِيدٌ وَمَغْفِرَةٌ مِّنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٌ وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلاَّ مَتَاعُ الْغُرُورِ" {الحديد/20}

“E mo pe dajudaju isemi aye yii je ere, ati iranu, ati oso, ati sise iyanran laaarin ara yin, ati wiwa opo dukia ati omo. (Iwonyi) da bi ojo (ti o mu irugbin jade), ti Irugbin re si n jo awon agbe loju, Leyin naa, yio gbe, iwo yo si ri i ni pipon, Leyin naa, yio di nnkan rirun (ti ategun maa fe danu), Iya to le ati aforijin pelu iyonu lati odo Olohun si wa ni orun, Ki si ni isemi aye yii bi ko se igbadun itanje” (Suurah al – Hadiid: 20)

Eleyi kosi tumo si ki a pinnu a ti dawa laini feyawo, tabi ki a ja arawa kuro nibi nnkan aye patapata, Islaam ti ko fun wa nipa eyi, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَابْتَغِ فِيمَا آتَاكَ اللَّهُ الدَّارَ الآخِرَةَ وَلاَ تَنسَ نَصِيبَكَ مِنَ الدُّنْيَا وَأَحْسِن كَمَا أَحْسَنَ اللَّهُ إِلَيْكَ وَلاَ تَبْغِ الْفَسَادَ فِي الأَرْضِ إِنَّ اللَّهَ لاَ يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ" {القصص/77}

“Wa ile ikeyin pelu ohun ti Olohun fun o, Ma se gbagbe ipin re ni ile aye, Ki o si maa se daadaa gege bi Olohun se se daadaa si iwo naa, Ma se wasise ibaje lori ile, Dajudaju Olohun ko feran awon obileje” (Suurah al – Qosoos: 77)

 Olohun ti ke wa pelu idekun Opolo ka fi le maa lo si’bi ohun ti o maa se wa lanfaani ni ile aye wa ati lorun, Sugbon, o je nnkan ibanuje pe opolopo eniyan kan n lo opolo yii sibi owo ohun ti o maa se won lanfaani aye nikan ni, koda ki o je pe yio pa awon anfaani awon elomiran lara, tabi ti O ko inira ba awon miiran, Iru awon iran eniyan yi ni Olohun ti o gbon – ngbon salaye pelu gbolohun re yi pe:

"يَعْلَمُونَ ظَاهِرًا مِّنَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ الآخِرَةِ هُمْ غَافِلُونَ" {الروم/7}

“Won nimo nipa ohun ti o han ninu oro isemi aye (yii) Afonu – fora si ni won nipa Ojo Ikeyin” (Suurah ar - Ruum: 7)

 Eni togbon ti o ni opolo ni eni ti O ba lo opolo re fun ohun ti yio se e lanfaani laye ati lorun, Pelu lilo O lati fi ri ohun ti O maa mu sorire laye re, nipa lilo gbogbo ohun ti Olohun da sile aye yii, fun anfaani ara re, ati idagbasoke isemi re, bakan naa nibi ki opolo mo ohun ti o maa fi agbara Olohun rinle fun un, ki o fi le maa gbaradi fun ohun ti o n reti leyin iku re.

Omoniyan wa bukata si ki o le daduro fun ra re, bakan naa ki o si ronu si nnkan ti o duro le lori nipa oro esin re, ko maa ba je pe oro esin maa pada dipe yio mu opolo eniyan maa tele esin tabi awon adisokan agbelero, to je iro, ti ki i se oro to dun gbo, ti o si je oro to yapa si laakaye to dape, Latari ebu laakaye ti Olohun bun eniyan lo fi le lagbara a ti se iyato laaarin ododo ati iro, ohun to bo soju ewon ati asise, Olohun ti fi opolo ke o nitori ki o fi ronu, ki i se nitori ki o fi maa tale elomiran pelu aimokan laise iwadi.

 O je ibanuje pe, eleyii ni ohun ti o n sele lodo opolopo eniyan ti O ri awon baba re ati awon baba baba re lori igbagbo kan, ati esin kan ti O si bere si ni tele won ni ti ajogunba, Ni India fun apeere, nbe ni ibe opopolopo igbagbo ti o tako opolo ti o ni alaafia, gege bi imaa sin awon eda bii: Awon eku, awon abe, awon maluu, awon okuta ati awon nnkan miran, Ikan lara awon onimimo so pe: "Gbogbo nnkan ni won n sin ni India ayafi Olohun nikan” ohun ti won gba lero pelu eyi ni pe awon esin to po ti ki i se esin Muslumi lo wa ni India, nitoripe awokose awon baba won ti won nse laise iwadii ni. awon irufe awon wonyi ni awon ti Olohun ti O gbon – ngbon ti Ola Re ga bu, ti o si salaye a i ni ri anfaani won Kankan (lori titele awon baab won pelu aimokan) pelu gbolohun Re pe:

"وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْاْ إِلَى مَا أَنزَلَ اللّهُ وَإِلَى الرَّسُولِ قَالُواْ حَسْبُنَا مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءنَا أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لاَ يَعْلَمُونَ شَيْئًا وَلاَ يَهْتَدُونَ" {المائدة/104}

“Nigba ti won ba so fun won pe: “E maa bo wa sibi nnkan ti Olohun sokale, (E maa bo wa) si odo Ojise, “Won a wi pe: Ohun ti a ba awon baba wa lori re ti to wa, “Se (ohun ti won yo maa wi niyen), ti o si je pe awon baba won ko nimo kan kan, won ko si mona” (Suurah al – Moo’idah: 104)

 Ki won O si ma lero pe mo n bu igbagbo awon miran, tabi pe mo n fi igbagbo won se yeye, rara o, Al – Qur’aan ti ko fun wa nipa eleyi, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَلاَ تَسُبُّواْ الَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ اللّهِ فَيَسُبُّواْ اللّهَ عَدْوًا بِغَيْرِ عِلْمٍ كَذَلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمْ ثُمَّ إِلَى رَبِّهِم مَّرْجِعُهُمْ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُواْ يَعْمَلُونَ" {الأنعام/108}

“E ma se bu awon nkan ti won n ke pe leyin Olohun, ki awon naa ma baa wa bu Olohun ni ti abosi ati ainimo, Bayen ni A se se ise ijo kookan ni oso fun won, Leyin naa, odo Oluwa won ni abo won, Nitori naa, (Olohun) yo si fun won ni iro ohun ti won n se nise” (Suurah al ‘Ani’aam: 108)

 Sugbon, afojusun mi ni pe ki awon eniyan mo esin ododo, ife mi si ni ki oore, Alaafia, ati irepo kari gbogbo awon omoniyan, ti mo si n beru igbeyin buruku lori won, eyi ti n reti eni ti o ba ku si ori ijosin fun elomiran leyin Olohun, tabi lori ofin ti o yato si ofin ti won so kale fun Muhammad (ki ike ati Ola Olohun maa ba a), ti Olohun si yonu si fun won.

 Ki o fi le de ibi ododo, lo opolo re, ati ironu re lori esin ti o n se e, ki o pasofo ni iwo nikan, ki o si doju ironu re ko ironu nipa Eni ti O ni awon sanmo, ati ile ati ohun ti Olohun da sibe, Ki O si je okan lara awon ti Olohun ti Ola Re ga so bayii nipa won:

"الَّذِينَ يَذْكُرُونَ اللّهَ قِيَامًا وَقُعُودًا وَعَلَىَ جُنُوبِهِمْ وَيَتَفَكَّرُونَ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ رَبَّنَا مَا خَلَقْتَ هَذا بَاطِلاً سُبْحَانَكَ فَقِنَا عَذَابَ النَّارِ" {آل عمران/191}

“Awon ti won n ranti Olohun ni inaro, ijoko ati ni idubule, won n ronu si iseda awon sanmo ati ile, (won si n so pe:) “Oluwa wa, iwo ko seda eyi fun iranu, Mimo fun O, Nitorina, so wa nibi iya Ina”. (Suurah aali – Imroon: 191)

 Ki paapa ohun ti Olohun ti Ola Re ga se alaye re nipa aida ile aye fun ere le han si o, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لاَعِبِينَ * مَا خَلَقْنَاهُمَا إِلاَّ بِالْحَقِّ وَلَكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لاَ يَعْلَمُونَ" {الدخان 38/39}

“Awa ko da awon sanmo ati ile ati ohun ti o wa laarin mejeeji fun iranu. * A ko da awon mejeeji bi ko se fun idi pataki, sugbon opolopo won ni ko mo” (Suurah a-d- Dukaan: 38 – 39)

Ododo ni pe won o da eniyan lasan ko fi wa je pe won o pa a lase, won o si ko fun un, won o ni san lesan, won o si ni fi iya je e. Olohun ti Ola Re ga so pe:

"أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لاَ تُرْجَعُونَ * فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ لاَ إِلَهَ إِلاَّ هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ" {المؤمنون 115/116}

“Se e lero pe A kan da yin fun iranu ni, ati pe eyin ko ni pada si odo wa?” * nitori naa, Olohun ga Oba Olola, Olododo, Ko si Olohun ti ijosin to si afi Oun naa, Oluwa (to da) Ite Alapon le * Eni ti o ba pe Olohun miran mo Olohun ko ni eri lowo lori re, dajudaju isiro – ise re si wa ni odo Oluwa re. dajudaju awon alaigbagbo ko ni jere” (Suurah al – Mu’miinuun:115 – 116)

 Pelu adamo isesi gbogbo eniyan nipa oro aye, ni pe ki eniyan maa se iwadi lori ewo ninu oro lo lola ju, ti o si pe ju lo, ati ohun ti yio je ki O ri oriire, boya nibi ohun jije tabi ohun mimu, aso wiwo, ati gbogbo igbadun aye, bakan naa, O to ki o tele ohun ti o ba nigbagbo si ati ohun ti esin re ba so, nipa bayii, ki o si se iwadi nipa esin ti o lola julo, ti o si pe julo eyi ti koni itakorawon Kankan, ti kosi tako adamo toni alaafia ati opolo to pe, eyi ti eniyan o maa ri oriire emi re nibe, ati ibale okan re, ati ifayabale, emi ndaju ipepe yi ko ire alaponle oluka iwe kekere y lati fi gbo agboye esin islam, , yio ri pe esin Imu Olohun – lokan ni, eyi ti ko tako adamo Kankan, ti kosi tako opolo Kankan, esin to se pe ti Olohun yonu si fun eda re, eyi kosi le je isoro fun o leyin ti Olohun ti fi o se konge, ayafi leyin ti o ba tu emi re sile fun ife – inu loku, ti o si tu sile fun ojukoko aye ati eyameya esin, Ki o wa dide lati se iwadi, ati kiko eko esin lati orisun ipile re eyi ti o ni alaafia, ati gbigba imo lati owo awon onimimo esin, ti won je olujosin fun Olohun, awon ti won se pe ki i se pe won n fi kikoni ni imo won wa oore aye bi ko se pe erongba won ni a ti fi wa iyonu Olohun, ati lati le yo awon omo – iya won kuro ninu inan, ki o si wa isora kuro lodo awon ti won ti so esin ati ofin – esin di orisun wiwa ije – imu, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"إِنَّ الَّذِينَ يَكْتُمُونَ مَا أَنزَلَ اللّهُ مِنَ الْكِتَابِ وَيَشْتَرُونَ بِهِ ثَمَنًا قَلِيلاً أُولَئِكَ مَا يَأْكُلُونَ فِي بُطُونِهِمْ إِلاَّ النَّارَ وَلاَ يُكَلِّمُهُمُ اللّهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَلاَ يُزَكِّيهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ {البقرة/174}

“Dajudaju awon ti won se apamo ohun ti Olohun sokale ninu Tira, won si n ta a ni owo pooku, awon wonyen ko je kini kan sinu won bi ko se Ina, Olohun ko si ni ba won soro ni Ojo Ajinde, ko si ni fo won mo, Iya eleta elero si wa fun won” (Suurah Al – Baqooran: 174)

 Ja emi re logun nibi iwadi nipa Olohun, ati nipa ododo to pamo fun o, O maa ri Olohun ni Alatileyin re, ti yoo maa fona mo o, ti yoo si maa to e sona, Fun oro Olohun ti Ola Re ga ti o so pe:

"وَالَّذِينَ جَاهَدُوا فِينَا لَنَهْدِيَنَّهُمْ سُبُلَنَا وَإِنَّ اللَّهَ لَمَعَ الْمُحْسِنِينَ" {العنكبوت/69}

“Awon ti won si n gbiyanju si oju-ona Wa, dajudaju Awa yoo fi won mo awon ona Wa, Ati pe dajudaju Olohun wa pelu awon oluse - rere” (Suurah al – Ankabuut’: 69)

 

 

SISA ESA TI O SORO

            Dajudaju yiyi esin pada ohun ti o soro ni ti omoniyan le se ninu isemi re, nipa wi pe oore ati aburu o maa se ifanfa ninu emi re, ati gbigba ati aigba, sugbon o ye ki eniyan pinnu sise re pelu gbogbo ohun ti o ba ni, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"وَيَوْمَ يُعْرَضُ الَّذِينَ كَفَرُوا عَلَى النَّارِ أَلَيْسَ هَذَا بِالْحَقِّ قَالُوا بَلَى وَرَبِّنَا قَالَ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ" {الأحقاف/34}

“(Ranti) ojo ti won maa seri awon ti won saigbagbo si inu Ina, (won si maa so fun won pe:) “Se eyi ki i se ododo bi? Won yoo wi pe: “Rara, (ododo ni) Oluwa wa” (Olohun maa) so pe: “Nitori naa, e maa to iya wo nitori pe eyin je alaigbagbo” (Suurah al – Ahqoof: 34)

Lo mo pe ojuona meji lo wa, ko pe meta, oju ona ti o ja si Alujannah, eleyi si ko le sele ayafi pelu ona odo ti awon Ojise – Olohun, ati Oju ona ti o ja si ina, eleyi ti o maa n sele latari ojuona titele ife – inu pelu mimu ife – inu ni Olohun, Apejuwe wa da gege bi okunrin kan ti o wa ni Orita ibi ti Ona ti pin yeleyele, ti ko mo ona eyi ti o maa to de ibi ti o n lo, titi ti okunrin kan fi de baa nibe, ti oun si je eni ti o mo ona ti o ye, nipa bayi, ti o toka re si oju ona to ye, bayi gele ni awon Ojise – Olohun ri,

Enmo bi aye nan se soro to, enmo bi isesi naa se le to, nigbati olugunri kuro nibi ase Olohun ba de, tabi eni ti O n sin Olohun lona to yato si ilana ijosin eyi ti awon Ojise Olohun mu wa, ti Olohun si yonusi fun awon eru re, ti yio ri isipaya awon ododo ati alaye isesi ti awon omode maa n hu ewu ni be, ati bi awon oloyun se maa bi omo ni be, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"هَلْ يَنظُرُونَ إِلاَّ تَأْوِيلَهُ يَوْمَ يَأْتِي تَأْوِيلُهُ يَقُولُ الَّذِينَ نَسُوهُ مِن قَبْلُ قَدْ جَاءتْ رُسُلُ رَبِّنَا بِالْحَقِّ فَهَل لَّنَا مِن شُفَعَاء فَيَشْفَعُواْ لَنَا أَوْ نُرَدُّ فَنَعْمَلَ غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ قَدْ خَسِرُواْ أَنفُسَهُمْ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُواْ يَفْتَرُونَ" {الأعراف/53}

“Ki ni won n reti bi kose (ojo) esan Re? Ni ojo ti esan Re ba de, awon ti won gbagbe re siwaju yoo wi pe: “Dajudaju awon Ojise Oluwa wa ti mu otito wa, Nitori naa, nje a le ri awon olusipe, ki won wa sipe fun wa tabi ki won da wa pada si ile aye, ki a le se ise miran yato si eyi ti a se?” Dajudaju won ti se emi won lofo, Ohun ti won si n da ni adapa iro ti di oro mo won lowo” (Suurah Al – A’raaf: 35)

 Ti eniyan o fi maa wa lero pe oun yio fi nkan ti o niyi ju ninu ohun ti oun ni laye paaro emi ara re, Olohun ti Ola Re ga so pe:

"يُبَصَّرُونَهُمْ يَوَدُّ الْمُجْرِمُ لَوْ يَفْتَدِي مِنْ عَذَابِ يَوْمِئِذٍ بِبَنِيهِ * وَصَاحِبَتِهِ وَأَخِيهِ * وَفَصِيلَتِهِ الَّتِي تُؤْويهِ * وَمَن فِي الأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ يُنجِيهِ * كَلاَّ إِنَّهَا لَظَى * نَزَّاعَةً لِّلشَّوَى * تَدْعُو مَنْ أَدْبَرَ وَتَوَلَّى * وَجَمَعَ فَأَوْعَى" {المعارج 11/18}

“Won o ri ara won, (won si maa dara won mo), Elese si maa fe ki oun fi awon omo re se irapada are re nibi Iya ni ojo ye * Iyawo re ati arakunrin re * Ati awon ebi re ti n gba a sodo nile aye, * Ati gbogbo eni ti o wa ni ori ile aye patapata, (elese yio fe fi won se irapada ara re nibi Iya), Leyin naa, (o maa fe) ki Olohun gba oun la (ninu iya ina), Rara! (ko le je bee), dajudaju, (Ina ti o maa wo ni) Ina Lathoo, ina ti n jo fofo * O maa bo awo ori toro * (Ina) ti yio maa ke si eni ti o keyin si (igbagbo ododo), o si se akojo (ko si naa fun esin)” (Suurah al – Mo’aarij: 11 – 18)

 Gbogbo eni kookan ni o mo pelu adamo re pe oore wa, aburu si wa, Gbogbo eni kookan wa lo si lagbara lati se yato laarin mejeeji pelu ebun opolo ti Olohun fun wa, gbogbo ofin – esin patapata lati sanmo lo je pe kosi nnkan ti o mu wa bi ko se pe o n pase Oore, ti o si n ko aburu, Gbogbo eda abara patapata omo – iya ni won nipa jije omoniyan, baba kan soso lo ko wo jo, iya kan soso naa lo si bi won, tori idi eyi lase n fe ki esin kan soso naa pawa po, esin kan soso naa si ni Islaam, eyi ti awon Anabi Olohun ati awon Ojise Olohun mu wa. Ki a si maa tele ofin – esin to keyin eleyi ti Olohun so eto ijoba aye naa kale pelu re, ki a sig be awon nkan agbelero ti won njosin fun bii orisa eyi ti Olohun ko pase ijosin fun, ki a si jinna si imaa gbe imaa fo awon eniyan mo, ki a si pada sibi imaa sin Olohun kan soso, ti koni orogun.

 

 

IPARI

            O ti daju pe O rorun ki omoniyan maa semi lori ‘le aye yii pelu alaafia, ki gbogbo won si maa wa ninu isemi igbadun, ninu ifayabale emi, ninu okan mimo, okan ife, iyen le ri bee nigba ti gbogbo won ba parapo sori esin ododo ti o se won ni erusin – Olohun, ti o ko bi gbogbo won o se dogba sinu, laiwo awon orisirisi awo ti won ni, Orisirisi ede ti won nso, ati orisirisi iran won, esin ti o ko jije Omoluabi won sinu, ti apa kan kofi ni le maa mu apa keji leru, ti agbalagba inu esin naa o fi le maa mu omode ibe leru, ti omode naa O si maa saponle agbalagba, ti won o si maa gbe titobi fun onimimo, bakan naa ti won o maa gbe aponle fun un, Ti enikankan kosi ni le se abosi, ti eni to je ole nibe o fi di alagbara titi ti won o fi gba eto re pada fun un, ti alagbara o si di ole tiit ti won fi gba eto eleto kuro lowo re, ti awon eniyan o si maa da (Amanah) ohun igba fi pamo pada, ti awon ese dida O si kere jojo, ti awon ese apanirun naa O si kere ni dida, ti awon emi, awon dukia ati awon omuluabi won o si maa ri idaabo bo, ti eniyan o maa sojukokoro lati se daada, nipa bayi ti yoo si maa pa awon eniyan lase daada sise, ti yoo si maa ko ibaje fun awon eniyan, ki isemi fi le duro, ki okan omoniyan si fi bale, eleyi ti a so yi ni ipin kekere ninu ipin nla ti n be ninu esin ododo, Gege bi mo se so tele pe awon ijo sohayuun lagbaye fe ki omoniyan jinna si esin yi, latari mimo ti ijo sohayuun ti mo pe gbogbo aye ti mo pe ogbon amusing ni o wa nibi ijo sohayuun, nitori pe iyapa, iseri kuro lori ododo, fifa eto omoniyan ya, lo ko sile,Tori pe ijo Sohayuun ti mo pe titanka Islaam ni iparun fun oun, bakan naa bi awon eniyan o se maa wonu Islaam lo yara julo, ti iyi re O fi kari aye, won o mo pe oro awon da bi eni ti o fe dowo bo Oorun ni, tori pe ohun to han daadaa ni ododo, nigba ti iro ki i pe lo titi, gege bi Olohun ti Ola Re ga ti so lori re:

"يُرِيدُونَ أَن يُطْفِؤُواْ نُورَ اللّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَيَأْبَى اللّهُ إِلاَّ أَن يُتِمَّ نُورَهُ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ" {التوبة/32}

“Won n fe lati fi enu won pa imole (esin) Olohun, Olohun si ko (fun won) ayafi ki O pe imole (esin) Re, awon alaigbagbo ibaa korira (re)” (Suurah Taohab: 32)

 Nipa bayii, fi opoo re ronu, ma je ki elomiran maa ba e ronu, je omoluabi nibi yiyan ohun ti o ye fun o lati se, mase je olutele elomiran lasan, ninu ohun ti o ti sele siwaju ri ni pe, ki imo aye ati idagabsoke too waye, awon eniyan maa n saroye nipa aimokan, sugbon nisinyi ko si aroye mo, nitori pe imo riri ti dirorun, agbaye si ti dabi ileto (ilu) kan, pelu awon ategun orisirisi ti o n be, bayii emi mo pe o le fe soro lati bo sinu ipile, sugbon o leto ki arojinle wa, tori pe esin Olohun to je esin ododo yio maa seku lo gbere ni titi ti asiko pipa aye re o fi to, je okan lara eni ti o se pe ti o ba ti teelorun yoo darapo mo awon eni re, ti okan re ba si bale lori nnkan kan, yoo pepe si nnkan naa, eleyii ni iroyin omoniyan to ye, ti o si baa mu, ti o nse iwadi nipa daada, ti yoo si maa takete si aburu, ododo ni oro Olohun ti o tobi julo, ti o so pe:

"هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَى وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ (33) " (الصف:9)

"Oun ni O ran ojise Re pelu onanmo ati esin otito, ki O le se afihan re lori gbogbo esin, koda ki awon olusebo kori re" (Suurah as-soff:9)

 Mo be Olohun ki O fi okan re mo ona, ki o tan imole si ojuona re, ki o si mu owo re lo sibi ododo, ope fun Olohun, Olutoju gbogbo eda, ki Ike ati Ola Olohun maa ba Anabi wa Muhamma, awon ara – ile re ati awon shabae re.

 

 

WWW.ISLAMLAND.COM