BILAL OMO RABAH APEJUWE FUN DEEDE ATI DOGBANDOGBA NINU ISLAM

BILAL OMO RABAH APEJUWE FUN DEEDE ATI DOGBANDOGBA NINU ISLAM

BILAL OMO RABAH
APEJUWE FUN DEEDE ATI DOGBANDOGBA NINU ISLAM

الإسلام ومكافحة التمييز العنصري – قصة إسلام الصحابي الجليل بلال بن رباح رضي الله عنه باللغة اليوروبا


Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

Itumo ni ede Yoruba
European Islamic Research Center (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Abd Ar-Razzaq Isa
Atunto
Ridwan Allah Murtadho
 
www.islamland.com

 

بسم الله الرحمن الرحيم
NI ORUKO OLOHUN, OBA AJOKE AYE, ASAKE ORUN
Ni asiko ti aimokan, igbesi aye eranko ati iwa ibaje di oun amuyangan laarin awon eniyan, gegebi: ima josin fun orisa, jija ogun ebi, jije oku eran, eleyameya, alagbara nfi iya je ole, olowo si n fiya je alaini ti apakan si nmu apakeji leru. Asiko yin ni Olohun gbe Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dide ni ojise. Ni kete ti o bere ipepe re ni awon iwa ibaje wonyii bere sii pare lawujo!
Eleyi si faa ti awon oniwabaje asiko yi (alabosi, olujegaba, ati oluje-owo-elomiran laileto) fi gbogun ti anabi. Ilana ati ofin ti anabi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) muwa da lori okansoso olohun, eyi ti o nmu awon eniyan puro nibi ijosin fun elomiran leyin olohun, ti o si nyowon kuro loko eru ati ijegaba, ilana ti o so gbogbo ibaje ati aimokan deewo, gegebi abosi, irenije ati gbogbo iran eleyameya, ilana ti o gbe aponle ati iyi fun omoniyan ti o si yoo kuro ninu iyepere ati iyanje awon amunisin.Siwaju ki anabi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) toode, omoniyan wa ninu imaa josin fun eniyan, okuta, aworan tabi igi, ti egbon si nso aburo deru latara ofin abosi. Esin Islam gbogun ti gbogbo ilana ati ofin eleyameya, ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope:
(يا أيها الناس ألا إن ربكم واحد وإن أباكم واحد ألا لا فضل لعربي على أعجمي ولا لعجمي على عربي ولا لأحمر على أسود ولا أسود على أحمر إلا بالتقوى)
''eyin eniyan okansoso ni olohun yin, okan si ni baba yin, ko si ola fun larubawa lori eni ti kii se larubawa bakan naa ni dudu ko si ni ola lori pupa bakan naa ni dudu ko ni ola lori pupa ayafi eni ti o bani iberu olohun''.
Awon iwe mimo awon Hindu (ijo barhamo) se afinrinle eleyameya laarin awon eniyan ni ibamu si eya ati iran ipinle. O wa ni akosile pe Barhama se eda iran Barhama lati ibi eya enu, o si da iran Kashtiri lati ibi eya apa, o si da iran Faisahi lati ibi eya itan, o si da iran Sudarahi lati ibi ese, awon iwe wonyi pin ise awon eniyan ni ibamu si awon iran wonyi, ti awon iran ti won da lati itan ati ese si wan ni ipo egbin ati iyepere, ti won si je omo odo fun iran Barhama.
Bakan naa ni awon asiwaju iran Roomu ati Giriki ni igbagbo wipe won da awon yato si gbogbo eda yoku, ti won si maa n pe awon eda yoku ni Al-barbari, eleyi waye ninu oro ojogbon Arosito nigba ti o so wipe; won da awon eda ni iran meji: iran ti o ni ogbon ati oye, awon naa ni iran Giriki, lati le je asoju ati asiwaju awon eda lori ile, ati iran ti o ni okun ati agbara awon naa ni Al-barbari (iran ti kii se iran Giriki) ti won da lati je eru fun iran ESA (Giriki). Awon yehuudi ati elesin kirisiti naa ri ara won gegebi ayanfe ti o ni ipo Pataki lodo olohun yato si awon eniyan yoku. Won si ma n wo awon eniyan yoku gegebi eni yepere ni ibamu si iran won. Awon Yehuudi ma npe awon eni ti kii se ara won ni Al-juwaimu (alaigbagbo, elebo ati elegbin). Won ni igbagbo mimu awon eniyan yoku leru toripe eni yepere ni won je. Olohun so eleyi ninu Al-Quran
وَمِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ مَنْ إِن تَأْمَنْهُ بِقِنطَارٍ يُؤَدِّهِ إِلَيْكَ وَمِنْهُم مَّنْ إِن تَأْمَنْهُ بِدِينَارٍ لَّا يُؤَدِّهِ إِلَيْكَ إِلَّا مَا دُمْتَ عَلَيْهِ قَائِمًا ۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا لَيْسَ عَلَيْنَا فِي الْأُمِّيِّينَ سَبِيلٌ وَيَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
'' o wa ninu awon ti a fun ni tira (yehuudi ati elesin kirisiti) eni to sepe ti won ba fi dukia pupo pamo si lodo yoo da pada, bakan naa eni ti o sepe ti won ba fi dukia kekere si lodo ko ni da pada ayafi pelu tipatipa, toripe won ma nsope: awon alaimokan ko ni eto lori wa, won si da adapa iro mo olohun ''. Qur'an3:75.
Ibn Kathir salaye oro yi pe '' oun ti o je ki won maa je eto eleto nipe won ni igbagbo wipe ko si aburu nibi jije dukia awon alaimokan (larubawa) toripe olohun ti se leto fun awon''. Olohun da esi oro yi pada fun won, ti o si salaye pe abara gegebi awon eniyan ni awon (yehuudi ati elesin kirisiti) naa je.
" وَقَالَتِ الْيَهُودُ وَالنَّصَارَىٰ نَحْنُ أَبْنَاءُ اللَّهِ وَأَحِبَّاؤُهُ ۚ قُلْ فَلِمَ يُعَذِّبُكُم بِذُنُوبِكُم ۖ بَلْ أَنتُم بَشَرٌ مِّمَّنْ خَلَقَ..."
 ''awon yehuudi ati elesin kirisiti sope: awa ni omo olohun ati ayanfe re''wi fun won pe; ki lo fa ti o fi nfiya ese yin jeyin? E ko je nkankan ju okan ninu awon eda re lo…. Qur'an5:18.
 Awon iran larubawa naa ko yato siwaju ki esin islam to de, won gba pe awon ni eya ti o pe julo, ti awon eya yoku si je eya yepere. Anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) se alaye aburu igbagbo wonyi, o si ko won leko imaa se aponle elomiran ati jijawo ninu iyepere won, eleyi ni ibamu si eko ati ilana esin islam. Umar (ki olohun ki o yonu si) sope Anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) sope ''
فعن بن عمر رضي الله عنهما قال: قال:" رأيت غنماً كثيرة سوداء دخلت فيها غنم كثيرةً بيض" قالوا: فما أولته يا رسول الله؟ قال:" العجم يشركونكم في دينكم وأنسابكم" قالوا: العجم يا رسول الله!! قال:" لو كان الإيمان معلقا بالثريا لناله رجال من العجم وأسعدهم به الناس.
 '' mo ri awon aguntan dudu ti o po ti awon funfun ti o po miran wo aarin won'' awon eniyan beere: kin ni itumo re iwo ojise olohun? O dahun wipe: awon ti kii se larubawa yoo maa wa pelu yin ninu esin ati iran yin, won tun beere wipe: awon ti kii se larubawa? O si dahun wipe: ti igbagbo ba sopo mo irawo ni oke sanmo awon kan yoo debe ninu awon ti kii se larubawa ti won yoo si se awon anfaani pelu re'' (al mustadraku idi 4 ewe 437)
 Orisirisi iran ni awon eniyan, iran kookan losi ni adamo tire. Olohun nikan ni o pe, sugbon omoniyan lo ni adinku ati aaye ayafi awon anabi olohun ati awon ojise re. Eko esin islam yi isesi awon musulumi pada ti o so won di olu se daada pelu awon eniyan. Al-mustaoridi Al-qurashi so fun Amru omo Al-a'si wipe oun gbo ti ojise olohun sope:
يقول الْمُسْتَوْرِدُ الْقُرَشِيُّ وهو عِنْدَ عَمْرِو بن الْعَاصِ سمعت رَسُولَ اللَّهِ  يقول:" تَقُومُ السَّاعَةُ وَالرُّومُ (الأوروبيون) أَكْثَرُ الناس" فقال له عَمْرٌو: أَبْصِرْ ما تَقُولُ (أي تأكد مما تقول) قال: أَقُولُ ما سمعت من رسول اللَّهِ  ،قال (أي قال عمرو بن العاص مصدقا لكلام المستورد ومعللا له): لَئِنْ قُلْتَ ذلك (أي أن التعليل لما قلته) إِنَّ فِيهِمْ لَخِصَالًا أَرْبَعًا إِنَّهُمْ لَأَحْلَمُ الناس عِنْدَ فِتْنَةٍ (أي العقل والتثبيت والصبر عند وقوع الفتن) وَأَسْرَعُهُمْ إِفَاقَةً بَعْدَ مُصِيبَةٍ (أسرعهم معرفة بعلاجها والخروج منها) وأَوْشَكُهُمْ كَرَّةً بَعْدَ فَرَّةٍ (أي المبادرة بالقتال بعد الهزيمة) وَخَيْرُهُمْ لِمِسْكِينٍ وَيَتِيمٍ وَضَعِيفٍ (في الإحسان إليهم) وَخَامِسَةٌ حَسَنَةٌ جَمِيلَةٌ (أي خصلة وصفة جميلة) وَأَمْنَعُهُمْ من ظُلْمِ الْمُلُوكِ (أنهم لا يظلمونهم ملوكهم). رواه مسلم
 '' opin aye yoo de nigbati yoo jepe iran Roomu (awon oyinbo) ni yoo po julo'' Amru sope '' se o ni amodaju lori oro yi? Al-mustaoridi si dahun wipe; mo n so oun ti mo gbo lenu ojise olohun, Amru dahun wipe; oun ti yoo fa oun ti o so niyi: isesi merin nbe lara awon eniyan wonyi; awon ni won ma n se laakaye, suuru ati iwadi julo nigba ti adanwo ba de, won si ma n tete mura ogun leyin ti won ba sewon logun, won ma n se daada si omo orukan, alaini ati ole eleekarun, won ni iwa ti o dara won kii se abosi awon olori won'' (Muslim).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) wa lati pa eleyameya run. Ije omoluwabi je okan ninu ipile esin Islam. Awon arole ojise olohun mereerin (Abu-Bakri, Umar, Uthman ati Ali) (olohun ko yonu si won) ba awon eniyan lo lasiko won laise opinya laarin olowo ati alaini, olori ati omo-eyin. Anas (ki olohun ki o yonu si) so nipa arakunrin kan omo Misro (Egypt) ti o wa fi ejo omo Amru (ki olohun yonu si) sun Umar lori wipe awon jo se idije ti oun si bori re, latari eyi o bere sii na oun legba ti o si n sope ''omo alaponle ni mo je''. Umar ranse pe Amru ati omo re, o si pa arakunrin Misro lase pe ki o na omo Amru pada, ti Umar si n sope: na omo alaponle, leyin nina yi Umar ni ki arakunrin yi tun na Amru, arakunrin yi si dahun pe: omo re lo nami mo si ti gbesan, Umar wa bi Amru wipe '' igbawo ni eso awon eniyan di eru ti won si biwon ni omoluwabi? Amru si dahun pe: mi ko mo nipa re won ko si so fun mi''. Islam pepe lo sibi dogbandogba laarin gbogbo omoniyan nitoripe ipile won okan naa ni, okunrin won ni tabi obinrin, alawo dudu ni tabi alawo funfun, larubawa ni tabi eni ti kii se larubawa. Olohun sope
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَاءً ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي تَسَاءَلُونَ بِهِ وَالْأَرْحَامَ
'' eyin eniyan eberu olohun ti o seda yin latara enikan soso ti o si da iyawo re latara re, ti o si tun da latara awon mejeeji okunrin pupo ati obinrin, eberu olohun eyi ti efi nbe ara yin…. " Qur'an 4:1.
 Ibikan soso naa ni ipile omoniyan tii se Adam. Olohun so ninu Al-Quran:
إِنَّ مَثَلَ عِيسَىٰ عِندَ اللَّهِ كَمَثَلِ آدَمَ ۖ خَلَقَهُ مِن تُرَابٍ ثُمَّ قَالَ لَهُ كُن فَيَكُونُ
 '' dajudaju apejuwe Isa (ike ati ola olohun ko maa ba) lodo olohun da gegebi apejuwe Adam (ike ati ola olohun ko maa ba) , Olohun da latara yerupe o si sope'' maa je bee'' o si nje bee'' Q3:59 ati
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ إِذَا أَنتُم بَشَرٌ تَنتَشِرُونَ
'' ninu awon amin re ni dida ti o da (baba) yin latara yerupe ti e si di omoniyan to fanka (si ori ile)'' Qur'an30:20.
 Won da gbogbo eniyan latara baba kan, ko si si ola fun enikan lori enikeji. Ojise olohun so bayi pe
ان الله عز وجل قد أذهب عنكم عبية الجاهلية (فخرها وتكبرها) وفخرها بالآباء مؤمن تقي وفاجر شقي والناس بنو آدم وآدم من تراب "
 '' olohun ti mu faari ati igberaga igba aimokan kuro laarin yin ati imaa se faari pelu iran, ninu ki eniyan je onigbagbo-ododo oluberu-olohun tabi elese oloriburuku, won da eniyan latara Adam, won si da Adam latara yerupe''(musnad Imam Ahmad). Olohun sope
وَمَا كَانَ النَّاسُ إِلَّا أُمَّةً وَاحِدَةً فَاخْتَلَفُوا ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ فِيمَا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
''omoniyan ko je nkankan ju ijo kan soso lo, sugbon won yapa, ti kii ba se oro toti siwaju lodo olohun re ko ba ti se idajo laarin won lori ohun ti won yapa le lori''. Qur'an 11:19.
 Bakan naa gbogbo omoniyan ni ipinle won wa lori esin kan soso ati ede kan soso, sugbon latara pipo si lonka won fonka si orile. Eleyi si se okunfa iyapa ede, awo ati adamo, latara oripa aye ikojo lara won. Eleyi naa lo si fa iyapa ilana-ironu, iwa, ije ati imu ati igbagbo. Idi niyi ti Olohun fi gbe awon ojise dide lati da awon eniyan pada si ipile won tii se imaa josin fun olohun nikan soso ti ko ni orogun. Olohun sope:
وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولًا أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاجْتَنِبُوا الطَّاغُوتَ ۖ فَمِنْهُم مَّنْ هَدَى اللَّهُ وَمِنْهُم مَّنْ حَقَّتْ عَلَيْهِ الضَّلَالَةُ ۚ فَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ
'' ati gbe ojise dide fun ijo kookan ki o maa so fun won pe: e maa josin fun olohun, e si jinna si orisa, o n be ninu won ti olohun fi mona, o si n be ninu won eni ti yoo sonu, e rin lori ile ki e woye si igbeyin awon ti o npe oro olohun ni iro'' Qur'an16:36.
 Esin Islam ko gbe ola fun aworan eniyan, Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
" رُبَّ أَشْعَثَ مَدْفُوعٍ بالأبواب (أي لا قدر له عند الناس فهم يدفعونه عن أبوابهم ويطردونه عنهم احتقارا له) لو أقْسَمَ عَلَى اللهِ لأَبَرَّهُ. " رواه مسلم
 '' melo-melo alaini ti irun re yoo ta koko, ti aso re yoo doti ti yoo si ti gbo, ti awon eniyan ko nii kaa kun, to si je pe toba fi olohun bura pe nkan yoo sele olohun yoo si je ki nkan naa sele''.(Al mustadrak ati Muslim). Ojise olohun salaye okunfa ti o je ki omoniyan yato ni awo, iran ati adamo, o so bayi pe
:" إن الله تعالى خلق آدم من قبضة قبضها من جميع الأرض فجاء بنو آدم على قدر الأرض منهم الأحمر والأسود والأبيض والأصفر وبين ذلك والسهل والحزن والخبيث والطيب "
 '' olohun da Adam latara yerupe ekunwo kan ti o bu latara gbogbo ile, awon omo Adam si mu gbogbo awon awo ti ile naa ni, pupa, dudu, funfun ati pupa resuresu, o wa laarin awon ile wonyi eyi ti o ro ati eyi ti o le koko, eyi to dara ati eyi to ko dara'' (Ibn Majah). Dogbandogba ni gbogbo omoniyan niwaju olohun oun kan soso ti o se iyato laarin won naa ni bi onikaluku ba se ntele ofin olohun si ati daada won ninu awujo. Olohun sope
يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَىٰ وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا ۚ إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ
 '' eyin eniyan a daa yin lati ara okunrin ati obinrin, a si seyin ni idile ati iran orisirisi ki e le da arayin mo, eni ti oni aponle julo ninu yin lodo olohun ni eni ti o beru olohun julo'' Qur'an49:13.
Olohun da awon eniyan ni iran ati idile nitori ki won le da ara won mo gege bi oruko enikookan, sugbon kii se lati fi gbe ola fun iran tabi ile kan lori ekeji. Olohun sope
وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَىٰ كَثِيرٍ مِّمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلًا
'' dajudaju ati pon awon omo Adam le, a mu won rin lori ile ati lori omi, a pese oun ti o dara fun won, a si gbe ola fun won lori gbogbo eda yoku'' Qur'an17:70.
Aponle yi ko gbogbo eniyan sinu laise opinya laarin won. Olohun sope
 وَهُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلَائِفَ الْأَرْضِ وَرَفَعَ بَعْضَكُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ
 ''olohun lo seyin ni arole lori ile ti o si gbe apakan ga ninu yin ju apakeji lo ''. Qur'an 6:165.
 Won seda gbogbo eniyan nitori ijosin fun olohun ati lati le maa se amojuto ori ile, ki won si maa role fun ara won, bo tile je pe won ju ara won lo ninu dukia nini, iwa, aworan, awo, daada sise ati aburu sise. Olohun so ninu Al-Quran
نَحْنُ قَسَمْنَا بَيْنَهُم مَّعِيشَتَهُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ وَرَفَعْنَا بَعْضَهُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ لِّيَتَّخِذَ بَعْضُهُم بَعْضًا سُخْرِيًّا
 '' awa la pin dukia laarin won nile aye, a si gbe apakan won ga ni ipo ju apa keji lo ki apakan le je oga fun apakeji'' Qur'an 43:32
 Awon eniyan ni ibamu si ilana esin Islam je deede ninu awon nkan wonyi;
 1. siso awon iwo ti o ba ofin esin mu ati nini eto si ominira ti o ba ilana esin mu, ti kii se ilana igbesi aye eranko eyi ti o se akoba fun awon ilu olaju ni abala eto iwa, eto awujo ati eto inawo.
 2. nibi ilana ofin laisi opinya eya, iran tabi awo. olohun so bayi pe
إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَن تُؤَدُّوا الْأَمَانَاتِ إِلَىٰ أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُم بَيْنَ النَّاسِ أَن تَحْكُمُوا بِالْعَدْلِ ۚ إِنَّ اللَّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُم بِهِ..."
 '' olohun payin lase pe ki e da dukia, (ti awon eniyan fi pamo si yin lodo) pada fun awon to ni won, ki e se idajo laarin awon eniyan pelu deede, ohun Pataki ni olohun payin lase re yi'' Qur'an4:58.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
:" أَيُّهَا الناس إنما أَهْلَكَ الَّذِينَ قَبْلَكُمْ أَنَّهُمْ كَانُوا إذا سَرَقَ فِيهِمْ الشَّرِيفُ تَرَكُوهُ وإذا سَرَقَ فِيهِمْ الضَّعِيفُ أَقَامُوا عليه الْحَدَّ وأيم اللَّهِ لو أَنَّ فَاطِمَةَ بِنْتَ مُحَمَّدٍ سَرَقَتْ لَقَطَعْتُ يَدَهَا
 '' eyin eniyan; dajudaju awon ti o siwaju yin parun latara pe ti eni ti o nipo ninu won ba jale won yoo fi sile sugbon ti eni yepere ba jale won yoo fi iya ofin je, mo fi olohun bura ti Fatima omo Muhammad ba jale maa ge owo re'' (Muslim).
 3. nibi ojuse ati esan ise rere, olohun sope
فَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًا يَرَهُ * وَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُ
 '' enikeni ti o ba se daada ti o kere bi omo inaagun yoo ri, bakan naa ni eni ti o ba se ise aburu ti o kere bi omo inaagun yoo ri. Qur'an 99:7&8.
 4. nibi eto si aponle jije omoniyan, a ko gbodo fi inira kan enikankan nitori awo, eya, ilana tabi igbagbo re. Olohun sope
وَلَا تَسُبُّوا الَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ فَيَسُبُّوا اللَّهَ عَدْوًا بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ كَذَٰلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِم مَّرْجِعُهُمْ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
'' e ma se bu awon ti njosin fun elomiran leyin olohun, ki awon naa ma se bu olohun lori aimokan, toripe ati se ise gbogbo ijo kookan ni oso fun won, odo olohun si ni ipadabo won ti yoo fun won labo ohun ti won se nise '' Qur'an6:108.
 5. nibi idaabobo dukia, iwo, omoluwabi ati eje won. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
:" ...فإن دِمَاءَكُمْ وَأَمْوَالَكُمْ وَأَعْرَاضَكُمْ بَيْنَكُمْ حَرَامٌ كَحُرْمَةِ يَوْمِكُمْ هذا في شَهْرِكُمْ هذا في بَلَدِكُمْ هذا لِيُبَلِّغ الشَّاهِدُ الْغَائِبَ فإن الشَّاهِدَ عَسَى أَنْ يُبَلِّغَ من هو أَوْعَى له منه"
 ''dajudaju, eje yin, dukia yin, omoluwabi yin je nkan owo laarin yin gegebi owo ojo oni (jimah), ninu osu yi (dhul-hijjah), ni ilu yi (makkah), ki eni ti o gbo ko so fun eni ti ko gbo…'' (Al- bukhari).
 6. nibi ileto si awon ipo idari laarin awujo ni ibamu si ikapani ati agbara lati fi se idari. Adiyu omo kindi sope ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
" يا أيها الناس من عمل منكم لنا عملا فكتمنا منه مخيطا فما فوقه فهو غال يأتي به يوم القيامة" فقام رجل أسود كأني أنظر إليه أراه من الأنصار قال: اقبل عني عملك يا رسول الله!! قال:" وما ذاك؟" قال: سمعتك تقول: الذي قلت قال:" وأنا أقوله الآن من استعملناه على عمل فليجىء بقليله وكثيره فما أوتي أخذ وما نهي عنه انتهى"
 '' eyin eniyan eni ti won ba lo fun ise kan ninu yin ti o wa mu ninu dukia naa lai leto oun to kere bi abere tabi oun ti o julo, ole onijanba ni eni naa yoo si gbesan ni orun, arakunrin dudu kan dahun odide o si wipe; ire ojise olohun, gba ise ti e fun mi lowo mi ! ojise olohun beere pe kilo de? O si dahun pe; mo gbo oun ti o so laipe yi, ojise olohun tun dahun wipe '' mo tun tun so bayi pe eni ti a bayan ise kan fun ki o ripe oun mu ninla ati kekere re wa fun wa, oun ti a ba fun ni kogba oun ti a ko ba fun ko gbodo mu'' (ibn Hiban).
 7. nibi sise anfaani ninu oun ti olohun da si aye. Olohun sope
يَا أَيُّهَا النَّاسُ كُلُوا مِمَّا فِي الْأَرْضِ حَلَالًا طَيِّبًا وَلَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ
'' eyin eniyan e maa je ninu oun ti o leto to dara lori ile, e ma si se tele ilana esu tori ota ti o fojuhan lo je fun yin'' Q2:168.
8. nibi ijosin fun olohun nikan soso, esin Islam wa fun gbogbo eniyan laifi awo, iran tabi eya se, toripe eru olohun ni gbogbo omoniyan. Olohun sope
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اعْبُدُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ
'' eyin eniyan e maa josin fun olohun oba yin, eni ti o da yin ati awon ti o siwaju yin'' Qur'an2:21.
 Anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) mu esin Islam wa lati pa gbogbo iran eleyameya re.
، فعن واثلة بن الأسقع قال: " قلت يا رسول الله ما العصبية قال ( أن تعين قومك على الظلم(
 Wathila omo Al-asqoa' sope; mo sope ire ojise olohun; kin ni a n pe ni eleyameya? O si dahun wipe'' ki o ran awon eniyan re lowo lori abosi'' (ibn Majah).
 Esin Islam ni ipile fun iba ara-eni se asepo lai ni mu eleyameya dani. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
" مَن قاتَلَ تحتَ رايةٍ عُمِّيَّةٍ، يُقاتلُ عصبيَّةً ، ويغضَبُ لعصبيَّةٍ ، فَقِتْلَةٌ جاهليَّةٌ "
'' eni to ba jagun nitori igbarata, tabi nitori eleyameya, tabi ti o n binu nitori awon eniyan re,(tosi ku sori re) ori aimokan lo ku si''.(An-nasai ati ibn Majah).
Ojise olohun fi ife han si Shuaibu omo ile Roomu, Salman omo ile Farisi ati Bilal omo ile Habasha, ni idakeji o fi ibinu ati ikorira pelu ota han si egbon baba re Abu Lahab eyi ti Al-Quran sokale lori sise adehun iya fun, olohun sope
تَبَّتْ يَدَا أَبِي لَهَبٍ وَتَبَّ * مَا أَغْنَىٰ عَنْهُ مَالُهُ وَمَا كَسَب * سَيَصْلَىٰ نَارًا ذَاتَ لَهَبٍ
'' owo Abi lahab ti gbofo osi ti sofo, ko ni se anfaani pelu dukia ati omo re, yoo si wo ina to n jo geregere'' Qur'an111:1-3.
 Al-Quran ti fi apejuwe lele lori awon musulumi ti o siwaju, Lukman ojogbon (olohun ko yonu si) ti o je eniyan dudu lati ile itopia ti odidi ogba oro Al-Quran sokale lori sise eyin ati ola fun, gegebi awon ogba oro ti o sokale loruko awon anabi ati awon eniire ti won ti siwaju, gegebi anobi Nuha (ike ati ola olohun ko maa ba), anobi Ibrahim (ike ati ola olohun ko maa ba), Al- Imran (olohun ko yonu si won), Maryam (olohun ko yonu si), anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) Yusufu (ike ati ola olohun ko maa ba),anobi Yunusa (ike ati ola olohun ko maa ba),anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba), ati beebe lo. Eleyi se afirinle ipile deede ati dogbandoga ti o wa ninu esin islam laifi eya tabi iran se.
 Ilu Habasha je ilu alawo dudu ni ile Afirika, ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) pa awon omoleyin lase sise Hijira (irin ajo esin) lo si ilu Habasha ni igba ti awon Quraishi fi inira kan won ni ibere ipepe esin Islam. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) so fun won pe
:" إنَّ بأرض الحبشةِ ملِكًا لا يُظلَمُ أحدٌ عنده ، فالْحقوا ببلادِه حتى يجعل اللهُ لكم فرجًا ومخرجًا مما أنتُم فيه "
 '' oba kan nbe ni ilu Habasha ti kii se abosi enikankan, e maa lo si ilu re titi ti olohun yoo fi mu aranse wa fun yin'' (As-silsilatu As-sahiha)
. Nigbati oba Habasha (An-najashi) ku ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
" صلوا عليه" قالوا يا رسول الله: نصلي على عبد حبشي (- أي ليس بمسلم-)!؟ فأنزل الله عز وجل:" وإن من أهل الكتاب لمن يؤمن بالله وما أنزل إليكم وما أنزل إليهم خاشعين لله لا يشترون بآيات الله ثمناً قليلا"
 '' e kirun si lara'' won si dahun pe; ire ojise olohun bawo la se maa kirun si eni ti kii se musulumi lara? Ni olohun ba so Al-Quran kale pe
وَإِنَّ مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ لَمَن يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْكُمْ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْهِمْ خَاشِعِينَ لِلَّهِ لَا يَشْتَرُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا
''dajudaju o nbe ninu awon ti a fun ni tira, awon ti o ni igbagbo si olohun ati oun ti won so kale fun yin ati oun ti won soke fun awon naa, ti won si beru olohun ti won kii si ta awon ami olohun ni edinwo'' Qur'an3:199 (As-silsilatu As-sahaiha).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
:" اسْتَغْفِرُوا لِأَخِيكُمْ" فصَفَّ بِهِمْ بِالْمُصَلَّى فَكَبَّرَ عليه أَرْبَعًا
'' e toro aforijin fun omo iya yin, won si to(saafu), won si kirun si lara'' (Al-Bukhari).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) fi apejuwe deede ati dogbandogba lele laarin awon omo leyin re, Usamah omo Zayd je eru anobi ti o tu okun eru lorun re, ti o si tun je omo eru anobi, eniyan dudu ti imu re pare-mole ni o je, ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) ma nko arakunrin yi papo mo Al-hasan ti o je omo Fatimah (olohun ko yonu si won) omo anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba), yoo si maa sope
"اللهم أحبهما فإني أُحِبُّهما"
''olohun ba mi nife won toripe mo nife won. Aisha ma nsope '' ko leto fun enikan lati korira Usamah, toripe ojise olohun ma nsope
'' من كان يحب الله ورسوله فليحب أسامة".
 '' eni toba nife olohun ati ojise re ko ya nife Usamah'' (Ahmad). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) tun sope
"مَنْ أَحَبَّنِي فَلْيُحِبَّ أُسَامَة''
'' eni to ba nife mi ko yaa nife Usamah'' (Muslim). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) je apere fun awon oun ti o ma nso, Aisha (olohun ko yonu si) sope
"أراد رسول الله صلى الله عليه وسلم أن يمسح مخاط (مخاط الأنف) أسامة فقلت: دعني حتى أكون أنا التي أفعل. فقال: "يا عائشة أحبيه فإني أحبه"
 '' ojise olohun fe nu ikun imu Usamah, mo wa sope; fi sile je kin nu'', ojise olohun dahun pe '' ire Aisha maa nife re toripe mo nife re'' (Al-Miskaat).
 Anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) fi Usamah se asiwaju omoogun musulumi lo si ile Roomu, o si fi se asiwaju omoogun ti awon agbalagba ati awon alaponle julo omoleyin anobi wa ninu won, eleyi tobi lara awon kan ninu won ti won si soro lori re, nigbati ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) gbo si eleyi o so bayi pe
:" إن تطعنوا في إمارته -أي إمارة أسامة- فقد طعنتم في إمارة أبيه من قبل، وأيم الله، إن كان لخليقًا للإمارة لجديرًا بها، وإن كان لمن أحب الناس إليَّ -يقصد زيد بن حارثة أبو اسامة- وإن هذا لمن أحب الناس إليَّ بعده"
 '' ti e ba fi enu abuku kan ije olori re, e ti fi enu abuku kan ije olori baba re ri, mo fi olohun bura pe o ni eto lati je olori o si ye bee, o je eni ti mo nife si julo (Zayd) bakan naa ni eleyi naa (Usamah)'' (Al-Bukhari ati Muslim).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) papoda siwaju ki omoogun Usamah to gbera lo si oju ogun, Abu-Bakri (olohun ko yonu si) si di arole akoko, ti o si pinnu mimuse asotele anobi lori ki Usamah je olori omoogun, pelu wipe Umar (olohun ko yonu si) jise awon Ansaar fun, sugbon Abu-Bakri (olohun ko yonu si) binu si isesi yi. Usamah tii se odo dudu gun esin niwaju awon omoogun ti Abu-Bakri si sin won jade nilu leni to n fese rin telewon (olohun ko yonu gbogbo won). Abu-Bakri toro iyonda lowo Usamah wipe ki o je ki Umar wa ni Medina pelu oun fun eto isejoba, o gba iyonda lowo Usamah pelu pe odo-mode ni! (Olohun ko yonu gbogbo won).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba), pelu pe abiyi ni ni adamo, iran, ati molebi ti o si ni aaye Pataki laarin awon larubawa, fi apejuwe deede ati dogbandogba lele. o si ma n sope
:" لاتطروني كما أطرت النصارى ابن مريم إنما أنا عبد فقولوا عبد الله ورسوله "
'' e ma se gbemi ga koja aaye mi gegebi awon elesin kirisiti se gbe Isa omo Maryam (ike ati ola olohun ko maa ba) koja aaye re, eru ni mo je, eru olohun ati ojise re'' (Al-Bukhari). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) fe omo egbon baba re (Zaynab omo Jahsh) fun eru re to so di omoluwabi (Zayd). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) lo gbogbo ona lati fi ipile deede rinle sinu okan awon omoleyin re, o ma n se ibeere nipa awon omoleyin re ni okookan laise opinya laarin won. Abu Hurayra sope
كانت امرأة سوداء تقم المسجد أو شاباً ، ففقدهما رسول الله صلى الله عليه وسلم ، فسأل عنها أو عنه ، فقالوا: مات ، قال صلى الله عليه وسلم:" أفلا كنتم آذنتموني؟" فكأنهم صغروا أمرها أو أمره، فقال:" دلوني على قبره " فدلوه فصلى عليه ، ثم قال:" إن هذه القبور مملوءة ظلمة على أهلها ، وإن الله تعالى ينورها لهم بصلاتي عليهم"
 '' arabinrin tabi arakunri kan ma n se amojuto mosalasi anobi, ojise olohun ko rii, o si beere nipa re, won so fun pe o ti ku ! ojise olohun si dahun pe '' kilo de ti e ko so fun mi? o da bi wipe won foju kere re, ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope'' e mu mi lo si ibi saare re, o si kirun si lara nigba ti o debe, o si sope '' awon saare wonyi kun fun okunkun fun awon eniyan re, sugbon yoo maa tan imole nigba ti mo ba kirun siwon lara'' (Al-Bukhari).
 Hakeem omo Hizaam sope ''anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) je eni ti mo nife si julo nigba aimokan, nigba ti o di ojise olohun ti o si se irinajo lo si ilu Medina, mo ri aso Dhi Yazin (okan ninu awon oba ti o ti je ni ilu Yaman) ti won ta ni aadota Dirham, mo si ra a lati fi se ebun fun ojise olohun, sugbon o ko lati gbaa gegebi ebun, Ubaydullah sope anobi sope '' awa kii gba ebun lowo elebo sugbon ao ra lowo won'' Hakeem wa si ilu Medina o si ri aso naa lorun ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) lori pepele (minbari) ti aso naa si wuyi pupo lara re, leyin igba naa ni ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) fun Usamah ni aso naa, Hakeem ri aso naa lorun re o si sope ''ire Usamah aso Dhi Yazin ni o wo yi? O si dahun wipe beeni toripe awa loore ju Dhi Yazin lo, baba mi loore ju baba re lo, iyami loore ju iya lo'' (Al-Mustadrak).
 Islam lo so Usamah di eni Pataki latara deede ati dogbandogba ti esin mu wa laarin gbogbo eniyan.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) ma njoko pelu awon omoleyin re ti yoo ma ba won soro, ba won se awada, ti yoo si maa beere nipa alamori won. O ma ngbo aroye won, o si ma nse atunse awon isesi ti o ba tako ilana esin ninu awon isesi won tabi awon oro won, ni Pataki julo awon to niise pelu imaa yepere tabi foju kere elomiran. Al-Ma'ruur omo Suwaid sope '' mo pade Abu Dharri ti o wo aso iru eyi ti omo odo re wo, mo wa bi leere wipe ki lo fa to fi ri bee? O si dahun wipe '' mo bu arakunrin kan pelu iya re, ojise olohun si so fun mi pe
"يا أبا ذرٍّ، أعيرتَه بأمِه؟ ، إنك امْرُوٌ فيك جاهليةٌ ، إخوانُكم خَوَلُكم ، جعلَهم اللهُ تحتَ أيديِكم, فمن كان أخوه تحتَ يدِه، فلْيُطعِمْه مما يأكُلُ ، وليُلْبِسه مما يَلبَسُ، ولا تُكلِّفوهم ما يَغلِبُهم، فإن كلَّفتُموهم فأعينوهم."
 ''o fi iya re bu? Iwa aimokan nbe lara re! awon omo-iya ninu esin ni awon eru wonyi, olohun o fiwon si abe ikapani yin, enikeni ti omo iya re ba nbe labe ikapani re, ko ya ma fun je ninu oun ti oun naa nje, ko si ma fun wo ninu oun ti oun naa nwo, e ko si gbodo fun won ni ise ti agbara won ko gbe, ti e ba wa fun ni ise ti agbara won ko gbe, e ya ran won lowo'' (Al-Bukhari).
 Bilal omo Rabah (olohun ko yonu si) je eru dudu lati ile Itopia, o pada ni ipo ati aaye giga ninu Islam, sugbon eleyi tun se alekun ire-ara-eni-sile ati fifun eleto ni eto re. Awon eniyan mo n wa sodo re ti won yoo si maa so ola ati ipin ti olohun se fun ninu oore, ti o ba ti ngbo awon eyin wonyi ni yoo si maa kilo fun emi re lati jinna si itanje ati igberaga, ti yoo si ma sunkun leni ti nso bayi pe '' mi o je nkankan ju omo Itopia ti o je eru teletele lo''. Nigba ti o si gbo pe awon eniyan nsope oun lola ju Abu-Bakri lo! O si so bayi pe '' bawo ni mo se le lola ju Abu-Bakri lo? nigba to je pe ninu awon dada re ni moje'' (Itan Damask ti ibn Kathir).
 O ma n wonu Ka'bah (ni asiko awon elebo) ti yoo si ma tuto si awon orisa ti o wa nibe ti yoo si maa sope ''eni ti o ba josin fun yin ti sofo ati adanu''. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) so fun pe omo al-Jannah(ogba idera) ni, ni igba ti won fe ki irun afemoju (aaro) o so bayi pe
" يا بِلالُ حَدِّثْنِي بِأَرْجَى عَمَلٍ عَمِلْتَهُ في الاِسْلامِ فَإِنِّي سمعت دَفَّ نَعْلَيْكَ بين يَدَيَّ في الْجَنَّةِ " قال: ما عَمِلْتُ عَمَلا أَرْجَى عِنْدِي أَنِّي لم أَتَطَهَّرْ طَهُورًا في سَاعَةِ لَيْلٍ أو نَهَارٍ إلا صَلَّيْتُ بِذَلِكَ الطُّهُورِ ما كُتِبَ لي أَنْ أُصَلِّيَ"
 '' ire Bilal so fun mi ise kan ti o ma nse ninu Islam ti o reti esan lori re lodo olohun? toripe mo gburo ese re niwaju mi ninu al-Jannah'' o si dahun pe '' mi o ni ise Kankan ti mo n rankan esan lori re jupe gbogbo igba ti moba ti se aluwala, laaro tabi losan, ni mo ma n kirun bi o ba se ro mi lorun'' (Al-Bukhari).
 Oun ati awon akegbe re ni Al-Quran so kale le lori, nigba ti awon abiyi Quraish wa sodo anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) ti won si ri pelu Bilal omo ilu habasha,Salman omo ilu farisi, Suaibu omo ilu ruumu ati awon miran gegebi ibnu Umi Abdul, A'maar, Khabbab (olohun ko yonu si won) ti won je alaini ninu awon olugbagbo ododo, won foju kere won ti won si so bayi pe ''a fe ki o fun wa ni aye pataki lodo re, ki o si fun wa ni aponle, toripe awon iko larubawa yoo ma wa, a ko si fe ki won maa ba wa pelu awon eru wonyi, ti a ba ti de sodo re ki won dide fun wa, ti a ba si ti setan pelu re ki o ma joko pelu won! Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) dahun wipe mo ti gbo, won si sope ki o ko iwe fun awon lori adehun yi, ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) fe ko iwe naa lati fi fa oju won si inu Islam ati lati fi le fun esin lagbara. Sugbon oro olohun sokale ni itako eleyi
وَلَا تَطْرُدِ الَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُم بِالْغَدَاةِ وَالْعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُ ۖ مَا عَلَيْكَ مِنْ حِسَابِهِم مِّن شَيْءٍ وَمَا مِنْ حِسَابِكَ عَلَيْهِم مِّن شَيْءٍ فَتَطْرُدَهُمْ فَتَكُونَ مِنَ الظَّالِمِينَ * وَكَذَٰلِكَ فَتَنَّا بَعْضَهُم بِبَعْضٍ لِّيَقُولُوا أَهَٰؤُلَاءِ مَنَّ اللَّهُ عَلَيْهِم مِّن بَيْنِنَا ۗ أَلَيْسَ اللَّهُ بِأَعْلَمَ بِالشَّاكِرِينَ * وَإِذَا جَاءَكَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِآيَاتِنَا فَقُلْ سَلَامٌ عَلَيْكُمْ ۖ كَتَبَ رَبُّكُمْ عَلَىٰ نَفْسِهِ الرَّحْمَةَ ۖ أَنَّهُ مَنْ عَمِلَ مِنكُمْ سُوءًا بِجَهَالَةٍ ثُمَّ تَابَ مِن بَعْدِهِ وَأَصْلَحَ فَأَنَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
'' ma se le jinan sio awon ti npe olohun won laaro ati losani, ti won si nwa ojurere ree, isiro ise won ko si lorun re, bakan naa ni ti iwo naa ko si lorun won, ti o ba fi le won jinan,oo wa ninu alabosi, bayi ni a fi apakan se won adanwo fun apakeji ki won le maa sope '' se awon eleyi ni olohun se idera fun lori wa?, nje olohun ko wa mo julo eni ti ndupe, ati awon ti won nigbagbo si awon ami wa, ti won ba wa si odo re so (fun won) pe '' alaafia ko ma je ti yin, olohun ti se ike sise (fun awon erure) lori arare ni oranyan, eni to ba se ibaje pelu aimokan ninu yin to wa ronupiwada leyin naa, ti o si se dada, dajudaju olohun ni oba alaforijin ti o si ma n keni'' Qur'an6:52-54.
Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) so iwe owo re sile o si sope ''alafia olohun ko maa bayin, olohun ti se ike sise (fun awon eru re) lori ara re loranyan''.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) ma njoko pelu awon omoleyin re yoo si dide nigbati o ba wu lati dide ti yoo si fiwon sille, olohun sope
وَاصْبِرْ نَفْسَكَ مَعَ الَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُم بِالْغَدَاةِ وَالْعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُ ۖ وَلَا تَعْدُ عَيْنَاكَ عَنْهُمْ تُرِيدُ زِينَةَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ
''se suuru pelu awon ti njosin fun olohun won laaro ati ni asale ti won si nwa ojuure olohun, mase gbe oju re kuro lodo won leni ti nwa oso aye ''
leyin naa ojise olohun ma njoko pelu won, ti o ba to asiko ti yoo dide awon naa yoo dide ki oun naa le dide. (Ibn Majah).
Tani ara habasha yi, ti o je eru lana, ti osi dii asiwaju loni latara gbigba islsmu re?
Eje ki a gbo itan re ninu tira arakunrin kan ti won npe ni khaalid Muhammad Khalid (ike olohun ko mo ba) so bayi:
 Bilal omo Rabah, akoko oluperun ninu Islam, ti o si ma nfi ohun rere ti o dun pe ipepe ododo, Bilal ti o ma nwoo awon orisa, ti gbogbo awon musulumi si nife re. Oje okan pataki ninu awon ise iyanu Islam. Bilal gbajumo ninu Islam dada, ti o fi jepe meje ninu mewa awon musulumi lo mo Bilal gegebi won se mo Abu-Bakri ati Umar (olohun ko yonu si won), ti won je arole meji akoko leyin anobi Muhammad ( (ike ati ola olohun ko maa ba). Awon omo kekere ti won wa ni ile iwe alakobere ko salai mo Bilal, yala ni ile larubawa, ile Afirika tabi ile alawo funfun. Won mo pe oun ni oluperun ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba), ti o si je eru ti olowo re ma n fi iya je pelu okuta gbigbona lati le seri re kuro ninu Islam, ti yoo si maa sope ':' okansoso, okansoso.
 Siwaju ki o to di musulumi, o je eru ti nda rakunmi oga re lori dabidun ekunwo meji… sugbon Islam so di eni iranti lailai. Igbagbo ododo ati titobi esin ti Bilal gbagbo si so di eni-itan ninu Islam ati laarin awon eekan, alaponle ati abiyi eniyan, koda opolopo awon abiyi, olowo ninu awon eniyan ni ko ni iru itan ati gbajumo lailai ti Bilal ni yi.
 Jije eni dudu ti iran re ko loruko ati ipo siwaju ko to di musulumi ko so di eewo fun lati di eni Pataki, eni eye leyin igba ti o dii musulumi ti o si se esin naa daada.
 Ero awon eniyan nipe eru ko je nkankan ju dukia olowo re lo, eni ti ko lola tabi leniyan, irinse si ni fun oga re ti ko si ni nkankan tabi le je nkankan lola. Sugbon oro ko ri bayi fun Bilal nigba ti o di onigbagbo ododo ti o si di asiwaju awon oluperun ninu Islam. Bilal je amin akin ati eekan. O je omo erubinrin dudu ti oruko re nje Hamamah, oun ati iya re je eru fun Umayah omo Khalaf ni ilu Makkah, lasiko yi igbese aye eru lo ngbe ti ko ni eto lori arare tabi agbiyele!!
 O bere si ni gbo nipa ipepe anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) lati odo awon ara Makkah, awon asiwaju won ati awon alejo won, ni Pataki julo lodo oga re tii se Umayah ti sii se okan ninu awon asiwaju ebi Jahmu. O ma nsoro pelu awon eniyan nipa anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) pelu ibinu ati ikorira. Ninu awon oro wonyi ni Bilal ti mo nipa esin Islam, eyi ti o kun fun imo olohun lokan, ipepe sibi iwa rere, deede ati ominira. Bakan naa ninu oro won ni Bilal ti mo pe anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) je alaponle, olododo, alafokantan ati oni laakaye eniyan. Won tun ma nso laarin ara won pe anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) kii se opuro, kii se alawo, kii si se were, sugbon awon ma nso eleyi lati fi ba loruko je ni, ki awon eniyan si le jinna si, atipe lati fi ran esin awon baba awon lowo ni, bakan naa lati fi daabo bo ipo iyi ati eye ti iran Quraysh wa, gegebi olu-ilu ijosin, aaye-owo ati ise hajji laarin gbogbo orikusu ile larubawa. Bakan naa lati se keeta awon iran Hashimi ti anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) jade laarin won.
Leyin eleyi Bilal gba odo anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) lo,o si kede Islam re fun. Sugbon igbesi aye yi pada fun Bilal, ile si fun mo leyin igba ti o di musulumi ti awon eniyan si mo si Islam re, Nigba ti oga re gbo si eleyi o binu pupo, o si mu ki o fi iya ti o le je Bilal. Yoo gbe Bilal sinu oorun osan gangan lero wipe eleyi yoo se okunfa ki o fi Islam sile, sugbon eleyi ko tu irun Kankan lara Bilal. O duro sinsin pelu gbogbo orisirisi awon iya ti won fi je, o si fi apere igbagbo ododo lele, nigbati o ba joko sinu emi ti o si ni asepo pelu olohun, bakan naa nipe ominira ati ije oga-emi ko see fowora.
Nigba ti ipepe esin Islam bere awon eniyan meje pere naa ni won se afihan Islam won: ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba), Abu-Bakri, A'maaru, Umu Sumayyah, Suaibu, Bilal, ati Al-Miqdad (olohun ko yonu si gbogbo won). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) ri idaabobo olohun lati odo Abu Talib, nigba ti olohun lo awon ebi Abu Bakri lati dabo boo, sugbon awon yoku bo si owo awon osebo ti won si nde won ni fila onirin ninu oorun osan gangan, ti won yoo si sa won si inu oorun gegebi aso tutu. Iya ti Bilal lo poju ti awon yoku lo, pelu pe won yoo fa le awon omode lowo ti won yoo si ma wo kaakiri aarin ilu Makkah ti yoo si maa sope '' okansoso, okansoso'' Won yoo gbe lori apata ni ihoho ninu oorun osan gangan, ti won yoo si maa da okuta gbigbona si lara, ki o le fi esin sile sugbon ero won ko jo lori re!!!
Ojoojumo ni iya Bilal nlekun ti o si nte siwaju, iya naa po debi wipe okan awon kan ninu awon ti o nfi iya naa je ko gba mo, ti won si ni ki Bilal maa lo lofe pelu majemu mima so dada nipa awon orisa won, ki o si maa pon won le, ki awon mo baa di eni yepere niwaju iran Quraysh. Bilal ko lati se oun ti won wi yi pelu pe o le se akoyo fun ninu iya ati iyepere, sugbon '' okansoso, okansoso'' naa ni o tun pariwo. Ti won ba sope '' so oun ti a nso'' yoo da won lohun pe '' mi o moo so ni'', won a si tun tesiwaju lori ifiyaje yi titi ile yoo fi su, nigba ti ile ba su won yoo so fun Bilal pe ko tun ero re pa ki ile to mo ki awon le fi sile toripe ifiyaje yi ti su awon naa, atipe o dabi enipe awon ni won fiya je ni. Sugbon Bilal ko ni ye lati maa so '' okansoso, okansoso''.
Isesi yi se alekun ibinu oga Bilal, o si so fun un pe '' maa fi e jofin fun gbogbo awon eru yoku, iwo eru buruku yi''. Iya naa ntesiwaju ti o fi di ojokan ti won gbe lori okuta ti o pon bi eye-ina, latara imu gangan oorun, ti o si se suuru ati ifarada. Abu Bakri (olohun ko yonu si) loo ba won nibi ti won tin fi iya jee ti o ni ki won ta fun oun, won si taa fun ni owo to ju iye owo re lo, toripe won lero pe tita re yoo se awon ni anfani ju iku relo (tori owo ti won yoo ri lori tita re). Abu-bakri ra kuro loko eru o si so di omoluwabi eniyan (olohun ko yonu si awon mejeeji). Nigbati Abu bakri mu Bilal de odo anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) ni omoluwabi, inu re dun pupo ni ojo naa, ojo yi si je ojo ajoyo nla fun un. Awon musulumi ti o gbagbo lasiko yi foju kan inira ti o po, eleyi lo si faa ti anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) fi ni ki won jade lo si ilu Medina ki won le ni ifokanbale ati alaafia kuro nibi inira awon Quraish.
Leyin igba ti anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) ati awon musulumi ni ifese- rinle ni ilu Medina won se irun pipe lofin. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) se esa Bilal fun irun pipe fun ohun re ti o dun, ti o si gun. Irun pipe naa lo bayi pe;
 Olohun lo tobi julo, olohun lo tobi julo,
 Olohun lo tobi tujo, olohun lo tobi julo,
 Mo jeri pe ko si eni to leto si ijosin ayafi olohun
 Mo jeri pe ko si eni to leto si ijosin ayafi olohun
 Mo jeri wipe Muhammad ojise olohun ni
 Mo jeri wipe Muhammad ojise olohun ni
 E je ki a lo kirun, e je ki a lo kirun
 E je ka lo si ona ola, E je ka lo si ona ola
 Olohun lo tobi julo, olohun lo tobi julo,
 Ko si eni to leto si ijosin ayafi olohun.
Ko dunmo awon osebo Quraish ninu bi esin Islam se n dagba soke ti awon musulumi si n po si. Eleyi fa ogun laarin awon iko Quraish ti o wa lati ba awon musulumi jagun ni ilu Medina.Oun ti o je amin ogun naa si ni '' okansoso, okansoso''. U'qbatu omo Abu Mui't ti o je eni ti o ma nse Umayah lakin lati fi iya je awon eru re, oun naa lo se okunfa iku re lojo ogun Badri lati owo Bilal.
 Umayah ko gbaradi lati lo si oju ogun Badri, sugbon U'qbah ni o se lakin ti o si gbo laya lati lo si ogun naa. Ojo ogun yii ni Umayah jere ise owo re lati owo Bilal.
Nigbati ogun bere, ti awon musulumi si bere si ni pariwo '' okansoso, okansoso'' inu Umayah baje lori wipe gbolohun ti o se okunfa iya ati iyepere fun eru oun lana ti wa di oun ti o fanka bayi! Ogun naa gbona girigiri, sugbon nigba ti ogun naa n sunmo ipari Umayah loo ba Abdur-Rahaman omo Aofu (olohun ko yonu si) pe ki o mu oun leru, lati le so emi re loju ogun. Nigbati Abdur-Rahman sin mu lo ni Bilal ri ti o si pariwo bayi '' olori awon keferi; Umayah omo khalaf '' o gbe ida re soke lati so ori re kale, Abdur-Rahaman si dahun wipe'' mo mu leru ni'' bayi ni Bilal pariwo ti o si so bayi pe '' eyin olu ran esin olohun lowo, olori awon keferi, Umayah omo Khalaf, ko si ona abayo fun loni'' awon musulumi si pe bo oun ati omo re won si pa awon mejeeji. Leyin eyi ni Bilal wo oku re nile ti o si npariwo '' okansoso, okansoso''.
Eleyi ti o sele laarin Bilal ati oga re yi je igbesan laaye ibi ti enikinni ti nwa ona lati pa enikeji re, loju ogun.
 Aaye ti enikan kii ti se amojukuro fun enikeji. Ti o ba se Umayah lo koko ni anfaani lati pa Bilal yoo se be laini iyemeji ninu.
Leyin odun die olohun gba ilu Makkah pada fun awon musulumi. Egberun mewa awon musulumi lo pada wo ilu Makkah! Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) gba Ka'bah lo ni kete ti o wo ilu Makkah, o si wo gbogbo awon orisa ti awon Quraish ko si inu ile naa, ti ounka won si se deede ounka ojo to wa ninu odun! Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) pelu Bilal wo inu ile naa, ti o si nso bi o se nwo awon orisa naa pe ''U'zzah, Laata ati Hubal ti pare, lati oni lo omoniyan ko ni fori bale fun orisa mo, olohun oba okansoso, oba ti o ga lola nikan ni won yoo ma sin''. O si wo orisa ti won se ni aworan anobi Ibrahim (olohun ko yonu si), ti o si nso pe
قاتلهم الله.. ما كان شيخنا يستقسم بالأزلام.. " مَا كَانَ إِبْرَاهِيمُ يَهُودِيًّا وَلَا نَصْرَانِيًّا وَلَكِنْ كَانَ حَنِيفًا مُسْلِمًا وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ "
 '' egbe olohun ko maa bawon '' anobi Ibrahim kii se elesin Yehudi, kii si se elesin kirisiti, sugbon o je olu mu olohun oba lokan soso ati musulumi ti ko si si ninu awon osebo'' Q3:67.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) pa Bilal lase pe ki o gun ori ile naa (Ka'bah) ki o si perun. Bilal perun lojo naa gbogbo ilu si dake roro ti won si nwi oun ti Bilal nwi pelu iberu olohun! Ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) ba awon eniyan soro, o si so bayi pe
" يامعشر قريش..ان الله قد أذهب عنكم نخوة الجاهلية (تفاخرها) وتعظمها بالآباء (التفاخر بالأنساب)..الناس من آدم وآدم من تراب"..
'' eyin iran Quraish, dajudaju olohun ti mu kuro fun yin imaa se igberaga ati ijora-eni-loju ti igba aimokan, Adamo ni ipile omoniyan, a si da Adamo latara yerupe. Abdullah omo Umar sope'' ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) baa won eniyan soro lojo ti o gba Makkah, o so bayi pe
: {يا أيُّها الناس ، إنَّ الله قد أذهب عنكم عُبِّيةَ الجاهلية ، وتعاظُمَها بآبائها ، الناس رجلان: بَرُّ تقي كريم على الله عزَّ وجل ، وفاجِر شقي هيِّن على الله عزَّ وجل، الناسُ كلَّهُم بنو آدمَ ، وخلَقَ الله آدمَ من ترابِ ، قال الله تعالى: { يا أيهُا الناس إنَّا خلقناكم من ذَكَر وأُنثى} إلى { إنَّ الله عليم خبير}
 ''eyin eniyan olohun ti mu kuro fun yin igberaga ati ijora-eni-loju ti igba aimokan ati ki a maa fi awon baba-eni se faari, ipin meji pere ni awon eniyan: eniyan rere, oluberu olohun, alaponle lodo olohun, ati obileje, oloriburuku, eni yepere lodo olohun, gbogbo eniyan je omo Adamo olohun si da Adamo latara yerupe, olohun so bayi pe ''eyin eniyan, a seda yin latara ako ati abo …. dajudaju olohun ni onimimo tii fun ni niro oun ti a se Q49:13'' (At-tirmidhi).
Ni ipari oro re ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
، يا أهل مكة ماذا تظنون أني فاعل بكم ؟ قالوا خيراً أخ كريم وابن أخ كريم !!
قال: اذهبوا فأنتم الطلقاء
''eyin ara Makkah ki le ro pe maa se fun yin loni? Won si dahun pe '' dada ni toripe alaponle omo alaponle ni iwo'' oun naa si dawon lohun pe '' e maa lo e ti di eni atusile''. Eleyi ya won lenu ti won si nse enmo lori isesi ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) yi, orisirisi ibeere lo njeyo lenu won; se Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) ati awon alaini ti a le jade nilu ko niyi sa? Se otito wa ni eleyi ti omoogun egberun mewa musulumi si nbe pelu re? se eni ti a gbogun ti ti a si le jade nilu ti a si pa awon ololufe re ni yi bi? Se oun lo si nba wa soro bayi peluu pe o ni anfaani lati gbesan lara wa? Ti wa nso fun wa pe ''e maa lo e ti di eni atusile''?
Bilal lo isemi pelu ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba), o si kopa ninu gbogbo ogun esin patapata, o je oluperun alamojuto ati olu daabobo awon oun owo esin Islam. Esin Islam ndagba soke beeni awon musulumi naa ndagba soke, Bilal lekun ni isunmo ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) titi ti o fi sofun pe omo al-jannah ni. Bilal koye kogbo ni alaponle, onirele eniyan ati oluteriba
. Umar omo Khatab (olohun ko yonu si), arole keji leyin ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) so ni ojo ti Abu bakri (olohun ko yonu si) ra Bilal kuro loko eru pe ''asiwaju wa ni Abu Bakri, o si ra asiwaju wa kuro loko eru''.
Nigba ti anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba) kuro laye ti Abu Bakri (olohun ko yonu si) si di olori awon musulumi, Bilal lo sodo re o si so bayi pe '' ire arole ojise olohun, ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) sope
:" رِبَاطُ يَوْمٍ وَلَيْلَةٍ خَيْرٌ من صِيَامِ شَهْرٍ وَقِيَامِهِ وَإِنْ مَاتَ جَرَى عليه عَمَلُهُ الذي كان يَعْمَلُهُ وأجرى عليه رِزْقُهُ وَأَمِنَ الْفَتَّانَ (عذاب القبر)"
 ''mimo wa ni oju ogun esin laaro ati ni ale lola ju awe ati irun oru odidi osu kan lo, ti o ba ku esan re yoo ma tesiwaju ati ije-imu re bakan naa yoo ni ifokanbale ninu iya saare'' Abu Bakri (olohun ko yonu si) beere pe '' ki lo fe?'' o si dahun pe '' mo fe lati maa jagun soju ona olohun, Abu Bakri (olohun ko yonu si) si dahun pe '' taani yoo ma perun fun wa?'' o si dahun wipe ''mi o ni perun fenikan leyin ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) '' Abu Bakri (olohun ko yonu si) sope '' duro ki o maa perun fun wa'' Bilal si dahun pe '' ire asiwaju awon olugbagbo ododo, ti o ba jepe tori ara re lo fi ra mi kuro loko eru, mumi sodo, sugbon to ba jepe tori olohun lo fi ra mi kuro loko eru, fi mi sile pelu olohun mi'' Abu Bakri (olohun ko yonu si) si dahun wipe '' tori olohun ni mo fi ra o kuro loko eru, tori olohun ni mo fi ra o kuro loko eru''.
 Bilal (olohun ko yonu si) lo si ile Shamu lati maa jagun soju ona olohun. Nigbati arole keji, Umar omo Khatab (olohun ko yonu si) be ile Shamu wo, awon musulumi beere fun ki o ni ki Bilal (olohun ko yonu si) perun fun awon. Umar pe Bilal (olohun ko yonu si gbogbo won) pe ki o perun toripe asiko irun tito, Bilal goke o si perun, eleyi pa gbogbo awon ti o wa nibe lojo naa lekun, ninu awon ti o semi pelu ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba), eleyi si ni akoko ati opin irun ti Bilal (olohun ko yonu si) pe leyin iku anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba). Ilu Shamu ni Bilal ku si. Nigba ti o nse aisan iku lowo iyawo re mo npariwo ibanuje, Bilal yoo si maa so fun pe '' idunnu lode'' gbolohun ti o si wi gbeyin ti o fi jade nipe '' a o lo pade awon ololufe lola, ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) ati awon emewa re''.
Bilal lo ogota odun ati die, won si sin si ite oku Damaski (olohun ko yonu si).
 Bilal, okan Pataki ninu awon eekan esin ti won da bi oke ti ko mira lori esin ati ifarada lori ododo. Eleyi ni igbega, eye ati iyi ti esin Islam nse fun awon olutele ilana re. Ipepe ododo to so okan omoniyan po mo olohun re, ti o so di olu fi arare sile fun olohun, ti o nje ki omoniyan gbagbe gbogbo inira ati wahala ti o le ri ni oju ona esin naa, koda o tun ma ndi igbadun-emi fun won, nitori orire lailai ti o sopo mo esin naa. Won mo pe orire naa bukata si suuru, akin ati igboya lati ri ayipada daada. Won mo wi pe oju ona al-jannah wa nibi titele anobi Muhammad (ike ati ola olohun ko maa ba), eni ti o la kuro nibi iro pipa, ijanba sise ati idale omonikeji.
Abu Sufyan omo Harbu (olohun ko yonu si), siwaju ko to di musulumi, so bayi pe '' Hiriqilu (oba Shamu) ranse pe oun ati iko onisowo lati inu iran Quraish ni ile Shamu, o pewa si ijoko awon eniyan nla ile Roomu, o si beere wipe '' ta ni alasunmo arakunri ti o npe arare ni ojise olohun ninu yin?, Abu Sufyan dahun wipe '' emi ni mo sun mo ju ni iran'' o si dahun wipe '' sun si bi'' o si dahun wipe '' mo fee beere nipa arakunrin yi lowo re, mo se paro fun mi'' Abu Sufyan sope '' ti kii ba se tori ojuti, ki won mo si so pe mo npuro, mi o ba paro mo''. Leyin eleyi lo wa beere awon ibeere wonyi:
 Bawo ni ebi re se je laarin yin? Abu Sufyan dahun wipe '' omo nibi niran niise.
 Nje enikankan ninu iran yin pe ara re ni ojise siwaju re? Abu sufyan dahun wipe ''rara''.
 Nje enikankan ninu awon baba re joba ri? Abu Sufyan dahun pe ''rara''
 Nje awon abiyi eniyan ni won ntele tabi awon alaini ati awon eni yepere? Abu Sufyan dahu wipe '' awon alaini ati awon eni yepere''
 Nje won nlekun ni onka ni tabi won ndinku? Abu Sufyan dahun wipe '' won nlekun si ni''
 Nje enikan sope oun o se esin naa mo ninu won bi? Abu Sufyan dahun wipe '' rara''
 Nje e mo si opuro laari yin siwaju ki o to pe ara re ni ojise olohun? Abu Sufyan dahun pe ''rara''
 Nje e mo si onijanba laarin yin? Abu Sufyan dahun wipe ''rara''
 Nje e jagun pelu re bi? Abu Sufyan dahun wipe '' beeni''
 Bawo ni awon ogun naa se ri? Abu Sufyan dahun wipe '' igbakan a o segun re, igba miran yoo segun wa''
 Kin ni awon oun ti o npayin lase re? Abu Sufyan si dahun pe ''e maa josin fun olohun kan soso, e ko gbodo se ebo pelu re, e gbe oun ti awon baba yin nso ju sile. O si tun ma npawa lase irun kiki, ododo siso, ilamojukuro (itelorun) ati imaa da okun ibi po''.
 Leyin naa ni oba naa dahun wipe '' mo bi o lere nipa iran re, o ni omo nibi niran ni, gege bee ni awon ojise olohun, inu iran abiyi laarin awon eniyan won ni won ti mo njade. Mo bi o leere, nje enikankan ninu yin so iru oro yi siwaju re? o si dahun wipe rara, ti o ba je pe enikan so siwaju re ni, mi o ba sope o nkose eni to siwaju re ni. Mo bi o leere wipe nje enikan ninu iran yin joba ri? O si dahun wipe rara. Ka ni beeni, mi o ba sope o fe gba ipo awon baba re ni. Mo bi o leere wipe nje e mo si opuro bi? O si dahun pe rara. Mo wa mo pe ko rorun fun anikan lati ma paro fun omoniyan ko wa mo paro nipa olohun. Mo bi o leere nipa awon to ntele, o si dahun wipe awon alaini ati awon eniyan yepere. Awon wonyi naa lo ma ntele awon anabi olohun. Mo bi o leere se won ndinku ni tabi won nlekun? O si dahun wipe won nlekun ni. Bayi nii oro igbagbo se ma nri titi ti yoo fi pe. Mo bi o leere wipe nje enikankan ninu won sope oun o se mo leyin igbagbo, o si dahun pe rara. Bi oro igbagbo se ri niyi nigba ti o ba wonu emi. Mo bi o leere nje oni ijanba ni bi? O si dahun wipe rara. Beeni awon ojise olohun won kii se ijanba. Mo tun bi o leere ki ni oun ti o npe yin si? O si dahun wipe mimo josin fun olohun kan soso, gbigbe ebo sise ju sile, e gbe oun ti awon baba yin nso ju sile. O ma npayin lase irun kiki, ododo siso, ilamojukuro (itelorun) ati mimo da okun ibi po''.
 Hiriqilu wa so bayi pe '' to ba jepe ododo ni oun ti o so wonyi, arakunrin naa yoo jogun ilu mi yi. Mo mo wipe won yoo gbe dide sugbon mi o mo pe aarin yin ni yoo je. Ka ni mo wa lodo re ni, mi o ba fi ara mi sile fun. Leyin naa lo gba iwe ti ojise olohun (ike ati ola olohun ko maa ba) fi ranse si, o si ka bayi ''
بِسْمِ اللَّهِ الرحمن الرَّحِيمِ من مُحَمَّدٍ عبد اللَّهِ وَرَسُولِهِ إلى هِرَقْلَ عَظِيمِ الرُّومِ سَلَامٌ على من اتَّبَعَ الْهُدَى أَمَّا بَعْدُ فَإِنِّي أَدْعُوكَ بِدِعَايَةِ الْإِسْلَامِ أَسْلِمْ تَسْلَمْ يُؤْتِكَ الله أَجْرَكَ مَرَّتَيْنِ فَإِنْ تَوَلَّيْتَ فإن عَلَيْكَ إِثْمَ الْأَرِيسِيِّينَ "قل يا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إلى كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ ألا نَعْبُدَ إلا اللَّهَ ولا نُشْرِكَ بِهِ شيئا ولا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا من دُونِ اللَّهِ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ "
ni oruko olohun, oba ajoke aye, oba asake orun, lati odo Muhammad eru ati ojise olohun si olola Roomu Hirikilu. Alafia (olohun ko yonu si) ma ba eni to ba tele oju ona ola, ju ara re sile fun olohun ki o le baa la ninu iya, olohun yoo si san o lesan ni ilopo meji. Sugbon ti o ba ko, ese gbogbo awon arisiyin (awon ara ilu re) yoo wa lorun re, '' sope eyin ti a fun ni tira, e wa sibi gbolohun to se deede laarin awa ati eyin, (eyi tii se) a ko gbodo josin fun elomiran leyin olohun, a ko gbodo se ebo pelu re, apakan wa ko gbodo mu apakeji ni olohun leyin olohun. Ti won ba ko lati se bee, e sofun won pe '' e je eleri wa pe musulumi ni wa'' Abu Sufyan sope '' leyin to soro tan ti o si ka iwe naa tan awon eniyan pariwo o si lewa jade, mowa so wipe oti gbabode gege bi omo baba kabsha se gbabode, (otumo si anobi muhammod) (ike ati ola olohun ko maa ba).

 
www.islamland.com