IWOYE ISLAM SI IBALOPO LAARIN OKUNRIN ATI OBINRIN

IWOYE ISLAM SI IBALOPO LAARIN OKUNRIN ATI OBINRIN

IWOYE ISLAM SI
IBALOPO LAARIN OKUNRIN ATI OBINRIN

نظرة الإسلام للجنس بلغة اليوروبا

 


Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة

 


Itumo ni ede Yoruba
European Islamic Research Center (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Abd Ar-Razzaq Isa
Atunto
Ridwan Allah Murtadho

 
www.islamland.com

 

بسم الله الرحمن الرحيم
Ni oruko olohun oba ajoke aye asake orun

OPE NI FUN OLOHUN. IKE ATI OLA KI O MA BA ANABI MUHAMMAD, AWON ARA ILE RE, ATI AWON OMOLEYIN RE
 Islam woye si iba ara-eni-lopo (laarin okunrin ati obinrin) gegebi oun Pataki ti sise re je oranyan, koda o tun je oun ti esin ni ife si, nigba ti a ba se ni ibamu si ilana ti olohun. Ko si ninu oun egbin ti omoniyan gbodo korira re. Olohun sope:
" زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ الشَّهَوَاتِ مِنَ النِّسَاءِ وَالْبَنِينَ وَالْقَنَاطِيرِ الْمُقَنطَرَةِ مِنَ الذَّهَبِ وَالْفِضَّةِ وَالْخَيْلِ الْمُسَوَّمَةِ وَالْأَنْعَامِ وَالْحَرْثِ ۗ ذَٰلِكَ مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَاللَّهُ عِندَهُ حُسْنُ الْمَآبِ
 '' Won ti se ni oso fun omoniya ojukokoro lara awon; obinrin, omo, dukia ti o po, wura ati adaka, esin ti o rewa, awon oun osin ati ile-oko ti o dara, eleyi je oun igbadun aye, sugbon odo olohun ni abo daadaa wa'' Q3:14.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope
 :"حبب إلي النساء والطيب وجعلت قرة عيني في الصلاة"
 '' won mumi nife obinrin ati orun didun (lofinda) won si fi itutu oju mi si ibi irun (kiki)'' (Al mustadrak, An-nasai, Ahmad).
 Esin islam ko fun ni, - latara pe o je esin ti o se deede pelu adamo omoniyan, - lati te adamo (ibalopo) yi ri, biko sepe o tun gbe awon ilana kale ti yoo je ki isesi naa lo bi o se to, ti yoo si mu anfaani igbadun wa, eleyi ti o yato si isesi eranko ti olohun binu si. Ibalopo yi le se okunfa ki omoniyan di ero inu ina nigba ti ko ba se e ni ona eto! Abu huraira (olohun ko yonu si) sope:
فعن أبي هريرة قال: سئل رسول الله صلى الله عليه وسلم عن أكثر ما يدخل الناس الجنة فقال:" تقوى الله وحسن الخلق وسئل عن أكثر ما يدخل الناس النار فقال الفم والفرج"
 '' won bi ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) leere wipe: kin ni oun ti yoo je ki awon eniyan wo ogba idera (al-janah) julo? O si dahun wipe ''iberu olohun ati iwa rere'' won tu beere wipe '' kin ni oun ti yoo gbe awon eniyan wo inu ina (jahanama) julo? O si dahun wipe ''enu ati abe (oju-ara)'' (At-tirimidhi).
 Iwe yi wa fun lati se alaye awon ona ti esin islam gbe kale lati fi fi eto si ona ibalopo laarin okunrin ati obinrin, atipe bawo ni yoo se je ijosin ti musulumi yoo gba esan dada lori re, ni igba ti o ba se e ni ibamu si ilana esin Islam.
 Abu dharri (olohun ko yonu si) sope awon eniyan kan ninu awon omoleyin ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
 فعن أبي ذر أن ناسا من أصحاب النبي صلى الله عليه وسلم قالوا للنبي صلى الله عليه وسلم: يا رسول الله ذهب أهل الدثور بالأجور يصلون كما نصلي ويصومون كما نصوم ويتصدقون بفضول أموالهم؟ قال:" أو ليس قد جعل الله لكم ما تصدقون إن بكل تسبيحة صدقة وكل تكبيرة صدقة وكل تحميدة صدقة وكل تهليلة صدقة وأمر بالمعروف صدقة ونهى عن منكر صدقة وفي بضع (المقصود به الجماع) أحدكم صدقة" قالوا يا رسول الله: أيأتي أحدنا شهوته ويكون له فيها أجر؟ قال:" أرأيتم لو وضعها في حرام أكان عليه فيها وزر فكذلك إذا وضعها في الحلال كان له أجرا "
 '' ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba), awon olowo ti ko gbogbo esan rere; won nkirun bi a se nkirun, won ngba awe bi a se ngba awe, won si tun ntore pelu eyi to seku ninu owo won? O si dahun wipe '' se kii se wipe olohun ti se oun ti e o fi mo tore fun yin ni bi; gbogbo afomo sise itore loje, gbogbo gbigbe olohun tobi itore loje, gbogbo didupe fun olohun itore loje,gbogbo siso pe '' ko si eni to leto si ijosin ayafi olohun itore loje, mimo pase daadaa itore loje, mimo ko iwa ibaje itore loje, bakan naa mimo se ibalopo (pelu awon iyawo yin) itore loje,'' won si dahun wipe '' ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) nje enikookan wa yoo ma je igbadun(ibalopo) yoo si tun mo gba esan daadaa lori re bi? O si dahun wipe '' nje e mo wipe ti o ba se lona aito yoo gbese bi? Gege bee naa nit i o ba se lona eto yoo gba esan daadaa'' (Muslim).
 Esin Islam se sise igbeyawo ni ona kan ti o to fun musulumi lati ni anfaani si ibalopo, o si se e ni ojukokoro sise igbeyawo naa. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" يا معشرَ الشبابِ ، منِ استَطاع الباءَةَ فلْيتزوَّجْ ، فإنه أغضُّ للبصَرِ وأحصَنُ للفَرْجِ ، ومَن لم يستَطِعْ فعليه بالصَّومِ ، فإنه له وِجاءٌ "
 '' eyin odo, eni to ba ni ikapa (inawo ati ibalopo) ninu yin ko lo se igbeyawo, tori wipe o mo nje ki a le reju sile, o si mo nje ki a le so abe (nibi agbere), eni ti ko ba ni ikapa ko ya mo gba awe, toripe o mo ndaabo boni (ninu agbere)'' (Al-Bukhari ati Muslim).
 Esin Islam ka igbeyawo, - fun enikookan laarin awujo, - si oun adamo Pataki lati le fi ni ifokanbale, ti o situn je ipile fun idagbasoke ife, imoo-ke-ara-eni,ati igbe ola fun enikeji, ninu awujo. Bakan naa lo tun je onan fun mimo po si fun eya omoniyan. Ni akotan o je okunfa fun iwa omoluwabi, iduro-sinsin awujo, iyi ati aponle enikookan ati gbogbo awujo. Eleyi lo fa to fi jepe kiko lati se igbeyawo je igbogun ti awon iwa eyin wonyi ati jijade kuro ni ibi oju ona adamo ati awujo eyi ti gbogbo omoniyan se deede nibe.
 Ninu awon oun afojusun ti esin islam fi se igbeyawo ni ilana niwonyi: ifokanbale, iduro-sinsin emi ati adamo laarin loko-laya. Olohun sope,
"وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِّتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ"
 '' ninu awon amin re (olohun), dida to da fun yin awon iyawo yin latara yin, ki e le mo fokanbale sodo won, o si se ife ati ike si aarin yin, dajudaju amin ni eleyi fun awon ti o mo nronu'' Q30:21.
 Bakan naa, o tun wa lati je iso ati idaabobo fun lokolaya kuro nibi awon iwa elegbin. Olohun sope:
"هُنَّ لِبَاسٌ لَّكُمْ وَأَنتُمْ لِبَاسٌ لَّهُنَّ"
 '' aso ibora(idaabobo) ni won (awon iyawo) je fun yin, ti eyin naa si je aso ibora fun won'' Q2:187.
 Eleyi lo fa ti esin Islam fi ri enikeni ti o ba tako ilana igbeyawo yi gegebi eni ti adamo ipile re ti yipada si aburu, ti won si npepe lo si ibi ibalopo ti ko ba ofin olohun mu. Esin Islam yato si igbesi aye eranko ti ko si ofin ati ilana ti won ntele nibi ibalopo laarin ara won. Ese nla ni ki omoniyan ba elomiran lopo lai leto (se igbeyawo). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" ما ظهرَ في قومٍ الزِّنا والرِّبا؛ إلَّا أحلُّوا بأنفسِهِم عذابَ اللهِ. "
 ''sina (ibalopo lai se igbeyawo) ati owo-ele ko ni gbajumo laarin awujo kan, biko-sepe won se iya olohun leto fun ara won''. Esin Islam nko awon omoniyan ni eko omoluwabi pelu imototo kuro nibi gbogbo iwa ati isesi elegbin, o si tun ngbiyanju lati fi ese won lele lo si ibi isesi ti o to, ti yoo je ki adamo won duro deede nibi iba-ara-eni-lopo. Abu umaamah sope:
فعن أبي أمامة قال: ان فتى شابا أتى النبي صلى الله عليه وسلم فقال: يا رسول الله ائذن لي بالزنا ؟!! فأقبل القوم عليه فزجروه وقالوا: مه مه فقال:" أدنه فدنا منه قريبا قال فجلس قال أتحبه لأمك قال لا والله جعلني الله فداءك قال ولا الناس يحبونه لأمهاتهم قال أفتحبه لابنتك قال لا والله يا رسول الله جعلني الله فداءك قال ولا الناس يحبونه لبناتهم قال أفتحبه لأختك قال لا والله جعلني الله فداءك قال ولا الناس يحبونه لأخواتهم قال أفتحبه لعمتك قال لا والله جعلني الله فداءك قال ولا الناس يحبونه لعماتهم قال أفتحبه لخالتك قال لا والله جعلني الله فداءك قال ولا الناس يحبونه لخالاتهم قال فوضع يده عليه وقال اللهم اغفر ذنبه وطهر قلبه وحصن فرجه فلم يكن بعد ذلك الفتى يلتفت إلى شيء.
 '' odo kunrin wa sodo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ti o so bayi pe ''ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) gbami laye ki nmo se sina?!! Awon eniyan doju ko arakunrin naa won si jagbe mo pe ki o gbe enu re dake. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) wa so bayi pe: ''sun si ibiyi, o si sun mo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba), o si so fun bayi pe: '' nje o fe ki won se iru re pelu iya re? o si dahun wipe rara, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope: ''awon eniyan yoku naa ko fe fun awon iya tiwon naa, o tun beere wipe '' nje o fe fun omobinrin re? o tun dahun wipe rara, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope; '' awon eniyan yoku naa ko fe fun omobinrin tiwon naa, o tun beere wipe '' nje o fe fun awon omo-iya re lobinrin? O si tun dahun wipe rara, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope: ''awon eniyan yoku naa ko fe fun awon omo-iya tiwon naa lobinrin, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) tun beere wipe '' nje o fe fun egbon tabi aburo baba re lobinrin bi? O si dahun wipe rara, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope: awon eniyan yoku naa ko fe fun awon egbon tabi aburo baba won lobinrin, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) tun beere wipe ''nje o fe fun egbon tabi aburo mama re lobinrin bi? O si dahun wipe rara, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope awon eniyan yoku naa ko fe fun awon egbon tabi aburo mama won lobinrin. O sope: ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) wagbe owo re le ni aya o si so bayi pe: ''olohun se aforijin ese re, ki o si mo emi re, kio so abe re (nibi sina). Lati igbayi odokunin yi ko boju wo sina. (Musnad Ahmad).
 Ko si ilana aini oko tabi iyawo ninu esin Islam, tabi ki a koyin si aye ati gbogbo igbadun ati awon nkan daadaa ti olohun se ni eto fun omoniyan ninu re. Anas sope:
فعن أنس بن مالك رضي الله عنه قال: جاء ثلاثة رهط (رجال) إلى بيوت أزواج النبي يسألون عن عبادة النبي فلما أخبروا كأنهم تقالوها فقالوا: وأين نحن من النبي قد غفر الله له ما تقدم من ذنبه وما تأخر قال أحدهم: أما أنا فإني أصلي الليل أبدا وقال آخر: انا أصوم الدهر ولا أفطر وقال آخر: أنا أعتزل النساء فلا أتزوج أبدا فجاء رسول الله فقال:" أنتم الذين قلتم كذا وكذا أما والله إني لأخشاكم لله وأتقاكم له لكني أصوم وأفطر وأصلي وأرقد وأتزوج النساء فمن رغب عن (ترك) سنتي فليس مني"
 ''awon okunrin meta kan wa si odo awon iyawo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) lati beere nipa ijosin re, leyin ti won dawon lohun tan, won wipe eleyi kere fun awon, won si sope '' ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) yato si awa toripe olohun ti se aforijin gbogbo ese re fun'', alakoko ninu won sope: '' emi yoo mo fi gbogbo oru kirun'', enikeji sope: '' emi yoo si mo gba awe lailai, mi o ni sinu'', eniketa si dahun wipe '' emi o jina si awon obinrin mi o si ni se iyawo lailai, igba yi ni ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) de, o si so bayi pe: '' eyin le nso bayi bayi! Mo fi olohun bura wipe emi ni mo paya olohun julo ti mo si beru re, sugbon pelu bee mo mo ngba awe mo si mo nsinu, mo mo nkirun loru mo si mo nsun, mo si mo nfe iyawo, eni to ba pa ilana mi ti kii se omoleyin mi'' (Al bukhari).
 Bakan naa ni esin Islam ko siso ara-eni di eniyan yepere lori igbadun ibalopo. Muhammad Qutub sope: ''ko si wahala lori oro ibalopo laarin okunrin ati obinrin ninu esin Islam. Esin Islam se amojuto gbogbo isesi adamo omoniyan ti ko si yo ibalopo sile. Esin Islam gbe ilana kale lori ibalopo lati fi le wa ni ibamu si enu-aala olohun ati lati wa ni iwontun-wonsi. Apejuwe ilana ti esin Islam gbe kale da gegebi afara to wa lenu (irinse idari omi) odo, won ko fi sibe lati di omi lowo sugbon lati dari re si awon ona ati aaye ni odiwon ti o ye. Eleyi si ni oun ti esin Islam nse pelu adamo omoniyan, pelu gbigbe awon ilana kale ti yoo wa ni iwontun-wonsi, ti ko si ni koja enu-aala olohun. Olohun sope: '' eleyi ni enu-aala olohun''. Titele ilana ti olohun la kale yi ni yoo mu ifokanbale ati oore wa fun awujo ati enikookan ninu awujo.
 Ilanan igbesi-aye aimokan naa mo pataki ki eto ati ilanan wa fun idari adamo omoniyan! Sugbon won fe ki adamo ibalopo laarin okunrin ati obinrin wa lai lofin ati ilanan, ki awon eniyan si ni ominira lati maa ba ara won lopo ni ilanan eranko! Ilanan igbesi-aye aimokan ko fi omoniyan sile ko se bo se wu lori dukia elomiran, tori wipe iya ofin nbe fun eleyi, bakan naa ni lori ilanan jije ati mimu, aso wiwo ati ile gbigbe!

IWOYE ISLAM SI IBALOPO LAARIN OKUNRIN ATI OBINRIN
Esin Islam woye si ibalopo laarin okunrin ati obinrin gegebi adamo pataki, ti sise re je oranyan ni ibamu si ofin olohun ti o da ako ati abo latara ato (omi-logbogbo), ti o si se igbeyawo ni ona kan gbogi to leto fun ibalopo lati waye laarin tako tabo, bakan naa ni o si tun wa won ni isora kuro nibi lilo ona miran ti o yato si igbeyawo lati se asepo. Olohun nigbati o nse eyin fun awon ti o ba tele ilanan yi sope:
قَدْ أَفْلَحَ الْمُؤْمِنُونَ * الَّذِينَ هُمْ فِي صَلَاتِهِمْ خَاشِعُونَ * وَالَّذِينَ هُمْ عَنِ اللَّغْوِ مُعْرِضُونَ * وَالَّذِينَ هُمْ لِلزَّكَاةِ فَاعِلُونَ * وَالَّذِينَ هُمْ لِفُرُوجِهِمْ حَافِظُونَ * إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِين * فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ
 '' dajudaju awon onigbagbo ododo ti jere, awon ti won ma nkirun pelu iberu olohun, ati awon ti won ma njina si oro ti ko wulo, ati awon ti won ma nse oun ti yoo fo won mo, ati awon ti won ma nso abe won (nibi sina sise), ayafi lodo awon iyawo won ati awon eru won (lobinrin) awon wonyi kii se eni abuku, sugbon eni to ba lo ona miran (yato si iyawo ati eru) awon wonyi ni olu koja enu-aala'' Q23:1-7.
 Olohun salaye wipe sise igbeyawo je oju ona awon ojise ati anabi olohun (ike ati ola olohun ko ma ba won) lati fi le se awon eniyan ni ojukokoro sise igbeyawo. Olohun sope:
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِّن قَبْلِكَ وَجَعَلْنَا لَهُمْ أَزْوَاجًا وَذُرِّيَّةً
 '' dajudaju a ti ran awon ojise siwaju re, a si se awon iyawo ati awon omo fun won'' Q13:38.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) se awon eniyan ni ojukokoro sise iyawo ati bibi omo, ki esin Islam le po ni ijo ki o si le maa seku. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:"تزوجوا الودود الولود فإني مكاثر بكم الأمم "
 '' e ma fe awon obinrin ti e nife ti won yoo si maa bimo, tori maa fi yin po ni ijo'' (Al-mustadrak).
 Bakan naa lo tun pawon lase ki won tete se iyawo fun eni to ba fe. Abu huraira sope: ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope;
" إذا أتاكم من ترضون خلقه ودينه فأنكحوه الا تفعلوا تكن فتنة في الأرض وفساد عريض "
 '' ti eni ti e nife si iwa ati esin re ba wa fun iyawo lodo yin, e yaa fun, bi beeko adanwo ati ibaje yoo sele lori ile'' (At-tirmidhi).
 Esin Islam gba awon obi ati alamojuto ni imoran ki won se eto inawo igbeyawo ni fifuye. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" إنَّ من يُمنِ المرأةِ تيسيرُ خِطبتِها وتيسيرُ صداقِها وتيسيرُ رحِمِها "
 '' ninu oun ti o ma nse okunfa ibukun (alubarika) fun obinrin ni sise biba soro ati owo ori re ni fifuye(irorun) olohun yoo se nini oyun ati bibimo re ni irorun'' (Ahmad).
 O si tun pawon lase sise igbeyawo, ki won ma si beru osi tabi aini. Olohun sope:
أَنكِحُوا الْأَيَامَىٰ مِنكُمْ وَالصَّالِحِينَ مِنْ عِبَادِكُمْ وَإِمَائِكُمْ ۚ إِن يَكُونُوا فُقَرَاءَ يُغْنِهِمُ اللَّهُ مِن فَضْلِهِ ۗ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ
 '' e se igbeyawo fun awon apon inu yin ati awon eni rere ninu awon eru yin lokunrin ati lobinrin, ti won ba je alaina olohun yoo rowon loro ninu ola re, olohun gbaaye ni imo'' Q24:32.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" ثلاثة حق على الله أن يعينهم المجاهد في سبيل الله والناكح يريد أن يستعف والمكاتب يريد الأداء "
 '' awon iran eniyan meta kan o je dandan ki olohun ran won lowo; olujagun si oju ona olohun, eni ti o se igbeyawo lati jina si ibaje, eru ti o fe ra ara re kuro loko eru lodo oga re ti o si gbero lati san owo ori ara re'' (Al-mustadrak).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si tun pa awon odo lase ki won tete se igbeyawo, o si salaye oun ti o le ran an eni ti ko ni ikapa lati se igbeyawo lowo lori adamo ibalopo. O so bayi pe:
:" يا معشر الشباب من استطاع الباءة فليتزوج فإنه أغض للبصر وأحصن للفرج ، ومن لم يستطع فعليه بالصوم فإنه له وجاء "
 ''mo pe eyin odo, eni to ba ni ikapa (inawo ati ibalopo) ninu yin ko ya lo se igbeyawo, tori wipe o mo nje ki a le reju sile, o si mo nje ki a le so abe (nibi agbere), eni ti ko ba ni ikapa ko ya mo gba awe, toripe o mo ndaabo boni (ninu agbere)'' (Al-Bukhari ati Muslim).
 Eni ti ko ba ni ikapa lati se igbeyawo latara ailowo lowo, esin Islam paa lase ki o ni amojukuro, ko si ko ara re ni ijanu nibi adamo re. Olohun sope:
"وَلْيَسْتَعْفِفِ الَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغْنِيَهُمُ اللَّهُ مِن فَضْلِهِ"
 '' ki awon ti won o ni ikapa lati se igbeyawo se amojukuro titi ti olohun yoo fi pese fun won ninu ola re'' Q24:33.
 Al-Quran fi apere ti o ga lele fun awon eniyan lati kose latara itan Anobi Yusufu nibi amojukuro ati iko-ara-eni ni ijanu nibi adamo ibalopo. Olohun sope:
" وَرَاوَدَتْهُ الَّتِي هُوَ فِي بَيْتِهَا عَن نَّفْسِهِ وَغَلَّقَتِ الْأَبْوَابَ وَقَالَتْ هَيْتَ لَكَ ۚ قَالَ مَعَاذَ اللَّهِ ۖ إِنَّهُ رَبِّي أَحْسَنَ مَثْوَايَ ۖ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُون * وَلَقَدْ هَمَّتْ بِهِ ۖ وَهَمَّ بِهَا لَوْلَا أَن رَّأَىٰ بُرْهَانَ رَبِّهِ ۚ كَذَٰلِكَ لِنَصْرِفَ عَنْهُ السُّوءَ وَالْفَحْشَاءَ ۚ إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُخْلَصِينَ "
 '' eni to wa nile re si gbiyanju lati ba se ibaje (zina), o ti ilekun o si so fun pe ''sun mo mi'', o si dahun wipe '' mo sa di olohun'' dajudaju (oko re) oga mi ni, o si fi mi si aaye to dara, (mi ko ni se abosi re) toripe alabosi koni jere. Okan re(arabinrin) ti fa mo (Anobi Yusufu), okan ti re naa si fa si, ti kii ba se imole olohun to ri, bayi ni a se mu aburu ati ibaje(zina) kuro fun. Dajudaju o je okan ninu awon eni esa''Q12:23-24.
 Koda Anobi Yusufu faramo ki oun jiya ati ki oun wo ewon ju ki oun se ibaje (zina) lo. Olohun sope:
 " قَالَتْ فَذَٰلِكُنَّ الَّذِي لُمْتُنَّنِي فِيهِ ۖ وَلَقَدْ رَاوَدتُّهُ عَن نَّفْسِهِ فَاسْتَعْصَمَ ۖ وَلَئِن لَّمْ يَفْعَلْ مَا آمُرُهُ لَيُسْجَنَنَّ وَلَيَكُونًا مِّنَ الصَّاغِرِينَ * قَالَ رَبِّ السِّجْنُ أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا يَدْعُونَنِي إِلَيْهِ ۖ وَإِلَّا تَصْرِفْ عَنِّي كَيْدَهُنَّ أَصْبُ إِلَيْهِنَّ وَأَكُن مِّنَ الْجَاهِلِينَ * فَاسْتَجَابَ لَهُ رَبُّهُ فَصَرَفَ عَنْهُ كَيْدَهُنَّ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ "
 '' arabinrin naa so bayi pe '' eni ti e ntori re bumi niyi, mo gbiyanju lati faa mora (fun zina) sugbon ko gba, ti ko ba se oun ti mo pa lase yoo wo ewon yoo si di eni yepere. (Anobi Yusufu) si so bayi pe '' ogba ewon temi lorun ju oun ti won npe si yi lo, ti o ba gbe ete won kuro fun mi, ma kosi inu (ibaje) won, ma si di okan ninu awon alaimokan''. Olohun gba adua re o si la nibi ete won. Dajudaju oun (olohun) ni olugbo ati onimimo''. Q12:32-34.
 Eewo ati ese nla ni fun omoniyan lati se ibalopo laise igbeyawo (zina) ninu esin Islam. Oloore fun omoniyan, nigba ti ko ba si ona abayo fun mo, ki o lo ona miran lati mu ato jade lara re (funrare), ju ki o se ibaje (zina) lo. Bi o tile jepe ese ni eleyi naa sugbon aburu re kere si ibalopo laise igbeyawo.

AWON ONA TI ISLAM GBE KALE LATI DAABO BO ADAMO IBALOPO
Esin Islam se gbogbo ona ti o ba le je okunfa itaji fun adamo ibalopo laarin awon ti won kii se oko ati iyawo ni eewo, ki won ma baa ko sinu ibaje gegebi ibalopo laarin okunrin ati obinrin, tabi laarin okunrin ati okunrin, tabi obinrin ati obinrin yala eyi ti a finnu-findo se ni tabi eyi ti a jeni nipa se, tabi mimu ato jade lara eni (funra eni). Ninu awon ona lati fi dena isesi aburu yi;
    Sise opinya laarin awon omokunrin ati omobinrin nibi ibusun. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" مروا الصبيان بالصلاة لسبع سنين واضربوهم عليها في عشر سنين وفرقوا بينهم في المضاجع "
 '' e pa awon omoyin lase irun nigba ti won ba di odun meje, e na won ti won ko ba kirun ti won ba di odun mewa, e si se opinya laarin won nibi ibusun''. (Abu Daud)

     Mimo wo aso eha (Hijab ati khimar) awon obinrin lodo awon okunrin ti kii se awon eleto won. Eleyi yoo so omoluwabi won yoo si gbe won jinna si imaa fi ewa won da adanwo sile fun awon okunrin. Olohun sope:
" يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قُل لِّأَزْوَاجِكَ وَبَنَاتِكَ وَنِسَاءِ الْمُؤْمِنِينَ يُدْنِينَ عَلَيْهِنَّ مِن جَلَابِيبِهِنَّ ۚ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَن يُعْرَفْنَ فَلَا يُؤْذَيْنَ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا

'' iwo ojise olohun sofun awon iyawo ati awon omore ati awon iyawo awon onigbagbo ododo wipe ki won ma lo aso eha won, eleyi lo to lati fi dawon mo, ki won ma si le fi inira kan won, olohun ni alaforijin onike'' Q33:59.
 Iyonda wa fun arugbo (ti ko bukaata si okunrin mo, ti okunrin ko si bukaata si oun naa mo) ki o bo aso eha (hijab tabi khimar) sile laini si irun sile, bakan naa o tun le si oju ati owo sile sugbon ki o bo lo dara julo. Olohun sope:
وَالْقَوَاعِدُ مِنَ النِّسَاءِ اللَّاتِي لَا يَرْجُونَ نِكَاحًا فَلَيْسَ عَلَيْهِنَّ جُنَاحٌ أَن يَضَعْنَ ثِيَابَهُنَّ غَيْرَ مُتَبَرِّجَاتٍ بِزِينَةٍ ۖ وَأَن يَسْتَعْفِفْنَ خَيْرٌ لَّهُنَّ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

''atipe awon arugbon ninu awon obinrin ti won ko ni bukaata si okunrin mo, ko si laifi nibi ki won bo aso eha won sile lai ni maa fi oso won sita, ki won si boo lo loore ju fun won, olohun ni olugbo ati onimimo'' Q24:60.

    O tun pase rireju sile nibi awon oun ti ko leto, lati so wiwo lasan kuro nibi wiwo ti ifekufe, ti o si tun le di ironu ibaje ti yoo wa yori si sise ibaje. Olohun sope:
قُل لِّلْمُؤْمِنِينَ يَغُضُّوا مِنْ أَبْصَارِهِمْ وَيَحْفَظُوا فُرُوجَهُمْ ۚ ذَٰلِكَ أَزْكَىٰ لَهُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا يَصْنَعُون * وَقُل لِّلْمُؤْمِنَاتِ يَغْضُضْنَ مِنْ أَبْصَارِهِنَّ وَيَحْفَظْنَ فُرُوجَهُنَّ وَلَا يُبْدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا مَا ظَهَرَ مِنْهَا

'' so fun awon onigbagbo ododo lokunrin ki won re oju won sile ki won si so abe won, eleyi lo mo julo fun won, dajudaju olohun yoo fun won niro oun ti won se. bakan naa, so fun awon onigbagbo ododo lobinrin ki won re oju won sile ki won si so abe won, won ko si gbodo fi oso han ayifi eyi to ba han funrare''Q24:30-31.
 Ibn-l-Qayyim (olohun ko ke) sope: ''nigba ti o jepe oju ni ibere ifekufe, olohun pa ase rire oju sile lati le so abe nibi isekuse(zina), toripe gbogbo isele patapata lo ma nbere lati ibi iran wiwo. Iran wiwo lakoko, ironu lo sikeji, igbese niketa, sise ibaje lo keyin gbogbo re. Tori eleyi ni won fi ma nsope '' eni to be gbiyanju lati so awon nkan merin ti so esin re; iran wiwo, ironu, oro-enu ati igbese".
 Idi niyi ti ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) fi so fun Aliy omo Abi-Talib (olohun ko (olohun ko yonu si) si) wipe:
" يا علي لا تتبع النظرة النظرة فإن لك الأولى وليست لك الآخرة "
 '' iwo Aliy ma se ma wo (obinrin) ni awo-tun-wo, olohun ko ni bere alakoko lowo re sugbon ese ni eleekeji'' (Al-mustadrak).
 Esin Islam se awon musulumi lakin lati le so oju won nibi iwokuwo, pelu adapada oore ti olohun yoo se fun won nibi rire oju won sile latara iberu olohun ati lati ri aanu re, Jareer omo Abd Allah sope:
" سألتُ رسولَ اللَّهِ صلَّى اللَّهُ عليهِ وسلَّمَ عن نَظرةِ الفجأةِ فقالَ اصرِفْ بصرَكَ "
 '' mo bi ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) nipa wiwo (obinrin) ni ojiji, o si dahun wipe '' gbe oju re kuro'' (Abu dawud).

    O tun pase ki a ma gba iyonda ki a to wole, ki oju omoniyan ma bari oun ti ko leto. Olohun sope:
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِيَسْتَأْذِنكُمُ الَّذِينَ مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ وَالَّذِينَ لَمْ يَبْلُغُوا الْحُلُمَ مِنكُمْ ثَلَاثَ مَرَّاتٍ ۚ مِّن قَبْلِ صَلَاةِ الْفَجْرِ وَحِينَ تَضَعُونَ ثِيَابَكُم مِّنَ الظَّهِيرَةِ وَمِن بَعْدِ صَلَاةِ الْعِشَاءِ ۚ ثَلَاثُ عَوْرَاتٍ لَّكُمْ ۚ لَيْسَ عَلَيْكُمْ وَلَا عَلَيْهِمْ جُنَاحٌ بَعْدَهُنَّ ۚ طَوَّافُونَ عَلَيْكُم بَعْضُكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ * وَإِذَا بَلَغَ الْأَطْفَالُ مِنكُمُ الْحُلُمَ فَلْيَسْتَأْذِنُوا كَمَا اسْتَأْذَنَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
'' eyin onigbagbo ododo, e je ki awon ti won nbe ni abe ikapani yin ati awon ti won ko tii balaga (to eni okunrin tabi eni obinrin) ma gba iyonda (ki won to wole) ni odo yin ni (awon) igba meta, siwaju orun asunbaa ati ni igba ti e ba nbo aso yin losan ati leyin irun ishai, awon asiko yi je asiko ihoho fun yin. Ko si laifi leyin awon asiko wonyi, ki apakan ma wole to apakeji. Bayi ni olohun n salaye awon amin (oro re), olohun onimimo ojogbon. Ti awon omokekere naa ba ti balaga (to eni okunrin tabi to eni obinrin) ki awon naa ma gba iyonda gegebi awon to siwaju won, bayi ni olohun n salaye awon amin (oro) re, olohun onimimo ojogbon. Q24:58-59.
     Esin Islam se leewo, ki okunrin ki o ma se bi obinrin tabi ki obinrin ma se bi okunrin. Ibnu Abas (olohun ko yonu si) sope:
فعن بن عباس رضي الله عنهما قال: لعن رسول الله صلى الله عليه وسلم المتشبهين من الرجال بالنساء والمتشبهات من النساء بالرجال.
 '' ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope: ibinu olohun ko ma ba gbogbo okunrin ti o nse bi obinrin ati gbogbo obinrin ti nse bi okunrin'' (Al-bukhari).

    O tun ko riri gbogbo oun to le je okunfa ki ara ko ma beere fun asepo, ninu ihoho okunrin tabi ti obinrin, bakan naa nibi awon aworan ti ko ba omoluwabi mu. Abd Allah omo Abi saeed Al-khudri sope ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" لا ينظرُ الرجلُ إلى عورةِ الرجلِ ، ولا المرأةُ إلى عورةِ المرأةِ ، ولا يُفضِي الرجلُ إلى الرجلِ في ثوبٍ واحدٍ ، ولا تُفضِي المرأةُ إلى المرأةِ في الثوبِ الواحدِ ."
 '' ki eyikeyi okunrin ko ma se ma wo ihoho okunrin miran, bakan naa ki eyikeyi obinrin ko ma se ma wo ihoho obinrin miran, ki awon okunrin meji ma se ma sun si abe aso kan na ni ihoho, bakan naa ki obinrin meji ma se sun si abe aso kan naa ni ihoho'' (Muslim).

    Esin Islam se mima gbo awon oun ti yoo ma se okunfa ki ara ma beere fun ibalopo ni eewo gegebi orin ati awon oun ti o jo. Toripe o ma nje okunfa ati igbese lati se ise-ese ni opolopo igba. Awon agbalagba onimimo islam ti so lati aye lailai wipe '' orin ni ofo (egede) zina''.

    Esin Islam ko fe ki a ma wo awon odo ti ko ni irungbo ti oju won jo ti obinrin ni awo-tun-wo ati mima joko pelu won pataki julo awon to rewa ninu won. Abu huraira sope ojisee olohun sope:
:" ... فالعينان زناهما النظر والأذنان زناهما الاستماع واللسان زناه الكلام واليد زناها البطش والرجل زناها الخطا والقلب يهوى ويتمنى ويصدق ذلك الفرج ويكذبه"
 ''… zina oju ni ki o wo(ibaje), zina eti ni ki o tete (si ibaje), zina awon ni ki o so (ibaje), zina owo ni ki o gbamu (ara ti ko leto si), zina ese ni ki o rin (lo si ibi ibaje), okan yoo fa mo yoo si gbero lati se ibaje, abe ni yoo si so di ododo tabi ki o pee niro'' (Muslim).

    Esin Islam se mimo dawa pelu obinrin ti kii se eleto eni ni aaye to pamo ni eewo, toripe o je ona ti esu fi le mu awon mejeeji se ibaje (zina) laarin ara won. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
 :".. ولا يخلون أحدكم بامرأة فإن الشيطان ثالثهما ..."
 '' enikeni ninu yin ko gbodo ma wa pelu obinrin ni aaye to pamo, toripe esu ni yoo siketa won'' (Ibn majah). Bakan naa lo se mimo wa papo obinrin ati okunrin ni eewo tori aburu ti o le jade lati ibi ipapo won yi gegebi zina, Muhammad Qutub sope: '' ipile mimo fidi-gbodi laarin okunrin ati obinrin sele latara wiwa iwosan fun pipa adamo ibalopo laarin awon alawo funfun (oyinbo). Awon onimimo nipa emi ati awujo ni won so asoju nipa anfaani ati daadaa ti won ro wipe yoo muwa fun awujo. Ni igba ti aburu isesi yi dele awon oyinbo ko le pada nibe mo. Sugbon awon onimimo nipa itoju pada nibi irori fidi-gbodi yi, eyi ti o ma nwaye nibi agbo ijo, ariya, inawo ati igbafe orisirisi koda niwaju awon obi ati awon oluko. Won pada sope gbogbo ifidi-gbodi laarin okunrin ati obinrin ni o ma nse okunfa fun ki ara ma wa ibalopo, sugbon ni igba ti aaye ko ba gba omoniyan lati se isesi yi ni awujo ti o wa laarin awon eniyan, gegebi eni ti ebi ibalopo npa, okan ninu nkan meji yoo sele; ninu ki o wa aaye miran ti ko ni si oun ti yoo di lowo lati se erongba re yi, tabi ki o wa ninu ibanuje wipe oun ko ri anfaani lati se ibaje naa''.

    Islam ko faramo ki iyawo ma se iroyin obinrin miran fun oko re, ki eleyi ma ba se okunfa ki okunrin naa korira iyawo re latara awon iroyin ti o wa lara obinrin ti iyawo re so nipa re, sugbon ti iyawo re ko ni awon iroyin wonyi, tabi ki esu tan an je lati se ibaje pelu arabinrin naa. Abdulah omo Masud sope: ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" لا تباشر المرأة المرأة كأنها تنعتها لزوجها أو تصفها لرجل كأنه ينظر إليها "
 '' ki eyikeyi obinrin ma se ma se iroyin obinrin miran fun oko re tabi okunrin miran gegebi igba (okunrin naa) nwo'' (Ibn Hiban).

    Islam ko fe ki obinrin ma fi oso re han ni gbangba si awon okunrin ti kii se eleto re. gegebi ki o lo lonfinda oloorun didun tabi ki o ma bo ihoho re bi o ti ye. Eleyi je okunfa fun ki okunrin ki o ma wo obinrin ni awo-tun-wo, o si ma nmu ara okunrin le, bakan naa lo si tun je okunfa fun ki omoniyan ko sinu ibaje. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" أيُّما امرأةٍ استعطرتْ ثُمَّ خَرَجَتْ ، فمرَّتْ علَى قومٍ ليجِدُوا ريَحها فهِيَ زانيةٌ "
 '' eyikeyi obinrin ti o ba lo lofinda (oloorun didun) ti o wa jade, ti o si gba odo awon eniyan ki won le gbo oorun re, alagbere ni iru obinrin bee'' (Ibn Hiban).
Bakan naa lo tun ko fun obinrin lati ma din ohun laarin awon okunrin. Idaabobo ni eleyi fun okan omoniyan nibi arun okan ti ma nfa iwa agbere. Oranyan lo je fun obinrin lati je ki oro re mo niwonba ki ohun re si lo sile. Olohun sope:
يَا نِسَاءَ النَّبِيِّ لَسْتُنَّ كَأَحَدٍ مِّنَ النِّسَاءِ ۚ إِنِ اتَّقَيْتُنَّ فَلَا تَخْضَعْنَ بِالْقَوْلِ فَيَطْمَعَ الَّذِي فِي قَلْبِهِ مَرَضٌ وَقُلْنَ قَوْلًا مَّعْرُوفًا
 ''eyin iyawo anobi, e o ri bi eni Kankan ninu awon obinrin, ti eba je oluberu olohun e ma ma din ohun yin nibi oro, ki emi eni ti arun nbe ninu okan re ma ba fa siyin, e si ma so oro to dara'' Q33:32.
 Olohun tun sope:
وَإِذَا سَأَلْتُمُوهُنَّ مَتَاعًا فَاسْأَلُوهُنَّ مِن وَرَاءِ حِجَابٍ ۚ ذَٰلِكُمْ أَطْهَرُ لِقُلُوبِكُمْ وَقُلُوبِهِنَّ
 '' ti e ba nbi won leere nkan, e bi won leyin gaga, eleyi ni yoo fo okan yin ati tiwon naa mo'' Q33:53.
 O si tun je eewo lati ma rin ni ihoho ati fifi awon aaye ti o le se okunfa adanwo lara sile. Olohun sope:
يَا بَنِي آدَمَ قَدْ أَنزَلْنَا عَلَيْكُمْ لِبَاسًا يُوَارِي سَوْآتِكُمْ وَرِيشًا ۖ وَلِبَاسُ التَّقْوَىٰ ذَٰلِكَ خَيْرٌ ۚ ذَٰلِكَ مِنْ آيَاتِ اللَّهِ لَعَلَّهُمْ يَذَّكَّرُونَ
 '' eyin omo Adamo a ti so aso kale fun yin lati ma fi bo ihoho yin ati lati je oso fun yin, aso iberu olohun lo loore julo, eleyi je ninu awon amin olohun ki won le ronu'' Q7:26.
Abu huraira sope ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
 "صنفان من أهل النار لم أرهما قوم معهم سياط كأذناب البقر يضربون بها الناس ونساء كاسيات عاريات مميلات مائلات رؤوسهن كأسنمة البخت المائلة لا يدخلن الجنة ولا يجدن ريحها وإن ريحها ليوجد من مسيرة كذا وكذا"
 '' awon iran meji omo ina niwon yoo je, sugbon mi o riwon (won ko si ni asiko re) : awon ijo ti won ni egba ti o dabi iru maalu ti yoo si ma fi na awon eniyan, ati awon obinrin ti won yoo ma wo aso sugbon ni ihoho won wa, won yoo ma mi okan awon okunrin ti won yoo si ma mi sotun-sosi ninu irin won, irun ori won yoo ga bi ike eyin rakunmi, awon wonyi ko ni wo al-jannah (ogba idera) bakan naa won ko ni gbo oorun re, ti yoo si ma run de ona to jin'' (Muslim).
 Esin Islam ti salaye awon to leto ninu awon okunrin lati ri oso obinrin kookan. Olohun sope:
وَقُل لِّلْمُؤْمِنَاتِ يَغْضُضْنَ مِنْ أَبْصَارِهِنَّ وَيَحْفَظْنَ فُرُوجَهُنَّ وَلَا يُبْدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا مَا ظَهَرَ مِنْهَا ۖ وَلْيَضْرِبْنَ بِخُمُرِهِنَّ عَلَىٰ جُيُوبِهِنَّ ۖ وَلَا يُبْدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا لِبُعُولَتِهِنَّ أَوْ آبَائِهِنَّ أَوْ آبَاءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوْ أَبْنَائِهِنَّ أَوْ أَبْنَاءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوْ إِخْوَانِهِنَّ أَوْ بَنِي إِخْوَانِهِنَّ أَوْ بَنِي أَخَوَاتِهِنَّ أَوْ نِسَائِهِنَّ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُنَّ أَوِ التَّابِعِينَ غَيْرِ أُولِي الْإِرْبَةِ مِنَ الرِّجَالِ أَوِ الطِّفْلِ الَّذِينَ لَمْ يَظْهَرُوا عَلَىٰ عَوْرَاتِ النِّسَاءِ ۖ وَلَا يَضْرِبْنَ بِأَرْجُلِهِنَّ لِيُعْلَمَ مَا يُخْفِينَ مِن زِينَتِهِنَّ ۚ وَتُوبُوا إِلَى اللَّهِ جَمِيعًا أَيُّهَ الْمُؤْمِنُونَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
 '' si so fun awon obinrin pe ki won ma re oju won sile,ki won si ma so abe won, won ko si gbodo fi oso won han sita ayafi eyi ti o ba han funrare, ki won si da awon aso won (khimar) bo awon egbe won, won ko si gbodo fi oso won han, ayafi si oko won, tabi awon baba won,tabi awon baba awon oko won,tabi awon omo won, tabi awon omo awon oko won, tabi awon egbo ati aburo won lokunrin, tabi awon omo awon egbon tabi aburo won lokunrin, tabi awon omo awon egbon tabi aburo won lobinrin, tabi awon obinrin akegbe won, tabi awon eru won ati awon omo-odo lokunrin ti won ko lagbara lati ba obinrin lopo, tabi awon omode-kunrin ti won ko da ihoho obinrin mo. Ki won ma se ma fi ese won lu ile nitori ki awon eniyan le mo oun ti won se si ese ni oso. E ronu pada sodo olohun (gbogbo yin) patapata eyin onigbagbo ododo, ki e le ba jere'' Q24:31.
 Esin Islam se irinajo fun obinrin ni oun nikan ni eewo nigba ti ko ba si okan ninu awon eleewo re pelu re gegebi oko re, baba re, egbon tabi aburo re lokunrin, tabi molebi re ti ko leto lati fe. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
 " لا يخلون رجل بامرأة ولا تسافرن امرأة إلا ومعها محرم" فقام رجل فقال: يا رسول الله اكتتبت (اسمي مكتوب في كشف الجند) في غزوة كذا وكذا وخرجت امرأتي حاجة (أي لكي تحج) قال:" اذهب فحج مع امرأتك"
''okunrin kan ko gbodo wa ni kolofin (koro) pelu obinrin bakan naa eyikeyi obinrin ko gbodo se irinajo ayafi pelu eleewo re'' arakunrin kan ba dide o si sope: 'ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) mo ti fi oruko sile lati lo si ogun bayi bayi iyawo mi si fe se hajji'' o si dahun pe '' ma lo ki o se hajji pelu iyawo re''(Al-Bukhari).
 Esin Islam gbe ilanan yi kale lati fi so ati lati fi daabo bo iyi ati aponle ti nbe fun obinrin. Irinajo ni opo igba ni o ma nmu inira ati wahala dani, Obinrin si je eda kan ti o le ni adamo ara latara awon nnkan bi sise nkan-osu, oyun, ifomoloyan, ati niti adamo emi gegebi itara, aanu, ati ki awon eniyan tabi awujo tete ni oripa lara won.
Obinrin ni bukaata si eni ti yoo daabo bo nibi aburu awon alaburu, toripe lopo igba obinrin kii le daabo bo ara re. bakan naa o tun ni bukaata si eni ti yoo ba gbo awon bukaata re ti yoo si je ki irinajo naa je irorun fun. Eleyi ni awon ojuse eni ti o ba ba obinrin se irinajo ninu awon eniyan ti a ka soke wonyi, ti aburu awon alaburu ko fi ni ba.
    Esin Islam se ofin wipe eni ti o ba ri obinrin ti ife re si ko si lokan ki o gba odo iyawo re lo lati lo gbo bukaata re lona ti o to, ko si le fi gbe royiroyi esu kuro ninu emi re. ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
".. فإذا أبصر أحدكم امرأة فليأت أهله فإن ذلك يرد ما في نفسه"
 '' eni to ba ri obinrin ninu yin, ko yaa lo gbo bukaata re lodo iyawo re, eleyi yoo le (royiroyi) eyi to wa ninu emi re lo'' (Muslim).
     Esin Islam pase ki ikookan ninu oko ati iyawo tete ma da enikeji re lohun ni igba ti o ba setan lati ba ni asepo. Eewo ni fun obinrin lati ko ibalopo pelu oko re. toripe isesi yi le se okunfa irori gbigbo bukaata re ni ona ti ko leto, tabi ki o dee mora, ti eleyi si le se okunfa aisan orisirisi. Tori idi eyi ni Islam fi fi owo ti o ni agbara mu oro naa. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" إذا دعا الرجل امرأته إلى فراشه فلم تأته فبات غضبان عليها لعنتها الملائكة حتى تصبح "
''ti okunrin ba pe iyawo re si ori ibusun (fun ibalopo) ti obinrin naa ko si wa, ti okunrin fi wa sun leni ti o nbinu si obinrin yi, awon malaika yoo ma se epe fun (obinrin naa) ti ile yoo fi mo'' (Muslim).
Bakan naa okunrin gbodo ma ba iyawo re lopo bi o ti ye, ki obinrin naa ma ba rin ona eewo lati te ara re lorun. Ibn Hazim sope: '' oranyan ni fun okunrin lati maa ba iyawo re se asepo, o kere ju eekan leyin nkan-osu re. ti ko ba se bee o di elese niwaju olohun. Olohun sope:
فَإِذَا تَطَهَّرْنَ فَأْتُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ أَمَرَكُمُ اللَّهُ
''ti won ba se imora (nibi nkan-osu) e wole towon (ba won lopo) ni ona ti olohun payin lase'' Q2:222.
Ninu eto obinrin ni ki o gbe oko re lo si ile ejo lati gba eto re fun, nigba ti ko ba ba lopo rara tabi ko se eto bi o tiye, ti eleyi si nmu inira ba obinrin naa. Islam se eleyi lati so awujo kuro nibi iwa ibaje (agbere).
    Olohun se ileri iya ti o le fun gbogbo eni ti o ba fe ki ibaje (agbere) di oun ti o gbajumo lawujo. Olohun sope:
إِنَّ الَّذِينَ يُحِبُّونَ أَن تَشِيعَ الْفَاحِشَةُ فِي الَّذِينَ آمَنُوا لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ"
'' dajudaju awon ti won fe ki ibaje fonka laarin awon onigbagbo ododo, iya ti o le lo nbe fun won laye ati lorun, olohun ni onimimo, eyin si je eni ti ko mo'' Q24:19.
Ni igba ti iya eni ti o nfe ki aburu tanka ba ri bayi, bawo ni iya eni tio se tabi ti o se iranlowo lori sise re yoo se ri?


IGBEYAWO NINU ESIN ISLAM

Esin Islam gbe ilanan kale lori sise esa iyawo. Igbeyawo je igbese pataki fun ipile molebi ati awujo ti o dara. Eleyi lo fa ti Islam fi ni ki omoniyan se esa awon iroyin ti yoo mu eso ti o dara jade ninu molebi ti enikookan ninu molebi naa yoo si je eni rere. Eso rere yi yoo ma jade lara obinrin ti o je elesin, omoluwabi, oluberu-olohun ati olu-pe iwo olohun lori awon oun ti olohun fi si abe ikapa re, bakan naa ti o si je olumojuto arare. Olohun sope:
" وَأَنكِحُوا الْأَيَامَىٰ مِنكُمْ وَالصَّالِحِينَ مِنْ عِبَادِكُمْ وَإِمَائِكُمْ ۚ إِن يَكُونُوا فُقَرَاءَ يُغْنِهِمُ اللَّهُ مِن فَضْلِهِ ۗ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ "
 '' e se igbeyawo fun awon apon aarin yin, ninu awon erukunrin ati erubinrin yin, ti won ba je alaini olohun yoo rowon loro ninu ola re, olohun ni oba to gbaye onimimo'' Q24:32.
 Ojise olohun salaye awon iroyin ti o ye ki omoniyan pataki ni igba ti o ba fe sesa eni ti yoo je enikeji re. eyi ti o pataki julo ninu awon iroyin wonyi ni ki a sesa eni to je elesin ati omoluwabi. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" تنكح المرأة لأربع لمالها ولحسبها ولجمالها ولدينها فاظفر بذات الدين تربت يداك"
'' awon eniyan ma nfe obinrin latari awon nkan merin; owo re, iran re, ewa re ati esin re, iwo jere pelu eni to lesin ki owo re ma ba gbofo'' (Al-Bukhari).
 
Esin Islam fe ki oko ri gege bi ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) se so pe:
" أكمل المؤمنين إيمانا أحسنهم خلقا وخياركم خياركم لنسائهم "
'' eni ti o pe julo ni igbagbo, oun ni eni ti iwa re dara julo, eni ti o loore julo ninu yin ni eni ti o dara julo si iyawo re'' (Ibn Hiban).
 Bakan naa ki iyawo ri bi ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) se so ni igba ti won bi leere wipe ewo lo loore julo ninu obinrin? O si dahun wipe:
" التي تسرُّهُ إذا نَظَرَ وتُطيعُهُ إذا أمرَ ولا تُخالفُه في نفسِها ولا في مالِهِ بما يكرهُ "
 '' eyi ti wiwo re ma ndun oko re ninu, ti o si ma ntele ase oko re, ti kii se oun ti oko korira, lori ara re tabi dukia oko re'' (Irwau –l- galeel).
 Islam fe lati gbe ile ti yoo duro lori ofin esin Islam duro. Eyi ti yoo je origun pataki lati gbe awujo duro lori daadaa. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" رحم الله رجلا قام من الليل فصلى وأيقظ امرأته فإن أبت نضح (رش بأطراف أصابعه) في وجهها الماء ورحم الله امرأة قامت من الليل فصلت وأيقظت زوجها فإن أبى نضحت (رشت بأطراف أصابعها) في وجهه الماء"
 '' ike olohun ki o ma ba arakunrin ti o ji ni oru ti o si kirun, ti o si ji iyawo re, sugbon ti ko ba dide yoo fon omi si loju. Ike olohun ki o ma arabinrin ti o ji ni oru ti o si kirun, ti o wa ji oko re, sugbon ti ko ba dide yoo fon omi si loju'' (Ibn Khuzaimah).

 

AFOJUSUN ISLAM LORI IGBEYAWO

Esin Islam fe lati se igbekale molebi ti okun re ko ni ja. Pelu wipe esin ati iwa omoluwabi ni ipile fun isesa eni ti a fe fi se enikeji, islam ko fowo yepere mu abala wiwo ewa naa. Eleyi lati je ki ikookan ninu okunrin ati obinrin se esa eni ti o ba te lorun ni ewa leyin esin ati ije omoluwabi. Islam se leto fun ikookan won ki o wo enikeji re siwaju ki won to fe ara won, ni wiwo ti o ba ofin olohun mu.
 Okunrin kan wa so fun ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) nipa arabinrin kan ti o gbero lati fe ninu awon Ansari (awon ara modina), ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) bi leere wipe
:" أ نظرت إليها ؟ " قال : لا ، قال صلى الله عليه وسلم :" فاذهب فانظر إليها فإن في أعين الأنصار شيئاً (أي في أعينهم صغر أو عمش أو نحو ذلك) "
 '' nje o ti wo daadaa?'' o dahun wipe rara, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope: '' lo wo daadaa toripe awon Ansari ma nni nkankan loju'' (Muslim).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) so anfaani ti o wa nibi ki a wo eni ti a gbero lati fe daradara.
 Anas sope Al-mugirah omo shuu'ba ba omobinrin kan soro fife, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) so fun wipe:
"اذهب فانظر إليها فإنه أجدر أن يؤدم بينكما "
 '' lo wo daradara toripe eleyi ni yoo je ki ife wa laarin yin lailai'' (Ibn Hiban).
 Bakan naa lati gbe awujo ti o dara duro, ti o si la kuro nibi awon iwa ibaje ati rogbodiyan orisirisi, Ni igba ti o je pe ife laarin okunrin ati obinrin je oun adamo ati ipile ninu islam, esin Islam faramo ife ti ko ba si lori iyapa olohun ati isesi eranko. Ninu oun ti o si ma nmu ife tojo ni oro ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) to sope:
" لَمْ يُرَ لِلْمُتَحَابَّيْنِ مِثْلُ النِّكَاحِ "
 '' ko si oun to dara julo laarin awon ololufe meji ju ki won fe ara won lo''.
 Koda Islam fe ki ase igbese ati igbiyanju lori bawo ni awon ololufe meji ti won je eni rere yoo se fe ara won, Omo Abas sope:
"أن زوج بريرة (كانت بريرة أمة وكان زوجها عبد) كان عبدا يقال له مغيث كأني أنظر إليه يطوف خلفها يبكي ودموعه تسيل على لحيته فقال النبي صلى الله عليه وسلم لعباس:" يا عباس ألا تعجب من حب مغيث بريرة ومن بغض بريرة مغيثا ؟ فقال النبي صلى الله عليه وسلم: لو راجعته "قالت يا رسول الله: تأمرني؟ قال:" إنما أنا أشفع "قالت لا حاجة لي فيه.
 oko Bariro je eru, oruko re si nje Mugith, mo ri ti o sare leyi Bariro ti o si nsunkun ti omije si nsan nibi irungbon re, ojise si so bayi pe ''ire Abas se ko wa ya-o-lenu iru ife ti Mugith ni si Bariro ti Bariro si korira Mugith? Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si so fun Bariro '' o si fe e pada'' o si dahun wipe '' ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) se o npami lase ni bi? Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si dahun wipe '' mo n sipe fun ni'' Bariro si dahun wipe '' mi o ni bukata si'' (Al-Bukhari).
 
Esin Islam fe ki baba tabi alamojuto omobinrin fi fun eni rere leyin ti o ba ti ba omobinrin naa soro ti oun nan si gba lati fe eni ti baba tabi alamojuto re fe ki o fe, Toripe ikookan ninu baba ati alamojuto lo je eni ti o ma nni akolekan igbayegbadun ati aseyori eni ti o wa labe ikapa re. Olohun so itan anobi Musa (ike olohun ko ma ba):
وَلَمَّا وَرَدَ مَاءَ مَدْيَنَ وَجَدَ عَلَيْهِ أُمَّةً مِّنَ النَّاسِ يَسْقُونَ وَوَجَدَ مِن دُونِهِمُ امْرَأَتَيْنِ تَذُودَانِ ۖ قَالَ مَا خَطْبُكُمَا ۖ قَالَتَا لَا نَسْقِي حَتَّىٰ يُصْدِرَ الرِّعَاءُ ۖ وَأَبُونَا شَيْخٌ كَبِيرٌ* فَسَقَىٰ لَهُمَا ثُمَّ تَوَلَّىٰ إِلَى الظِّلِّ فَقَالَ رَبِّ إِنِّي لِمَا أَنزَلْتَ إِلَيَّ مِنْ خَيْرٍ فَقِيرٌ* فَجَاءَتْهُ إِحْدَاهُمَا تَمْشِي عَلَى اسْتِحْيَاءٍ قَالَتْ إِنَّ أَبِي يَدْعُوكَ لِيَجْزِيَكَ أَجْرَ مَا سَقَيْتَ لَنَا ۚ فَلَمَّا جَاءَهُ وَقَصَّ عَلَيْهِ الْقَصَصَ قَالَ لَا تَخَفْ ۖ نَجَوْتَ مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِين * قَالَتْ إِحْدَاهُمَا يَا أَبَتِ اسْتَأْجِرْهُ ۖ إِنَّ خَيْرَ مَنِ اسْتَأْجَرْتَ الْقَوِيُّ الْأَمِينُ * قَالَ إِنِّي أُرِيدُ أَنْ أُنكِحَكَ إِحْدَى ابْنَتَيَّ هَاتَيْنِ عَلَىٰ أَن تَأْجُرَنِي ثَمَانِيَ حِجَجٍ ۖ فَإِنْ أَتْمَمْتَ عَشْرًا فَمِنْ عِندِكَ ۖ وَمَا أُرِيدُ أَنْ أَشُقَّ عَلَيْكَ ۚ سَتَجِدُنِي إِن شَاءَ اللَّهُ مِنَ الصَّالِحِينَ * قَالَ ذَٰلِكَ بَيْنِي وَبَيْنَكَ ۖ أَيَّمَا الْأَجَلَيْنِ قَضَيْتُ فَلَا عُدْوَانَ عَلَيَّ ۖ وَاللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ
'' nigba ti o de ibi omi (kanga) Madiyana o ba awon eniyan ti won fun awon eran won ni omi mu, o si ri awon omobinrin meji ti won duro loto, o bi won leere wipe '' ki lo seyin (ti e ko fun awon eran tiyin lomi)? Won dahun wipe '' a ko le pon omi ayafi ti awon wonyi ba setan, (toripe) baba wa si ti darugbo * o ba won pon omi, o si gba iboji lo, o si sope olohun mi, mo bukata si eyikeyi oore ti o ba sokale fun mi.* leyin naa ni okan ninu awon (obinrin) mejeeji wa sodo re, ti o si nrin leni ti o ntiju. O si sope '' baba mi npe o lati san o lesan omi ti o ba wa pon. Nigba ti o de odo re ti o si so itan fun, o so fun pe '' ma beru. O ti la lodo awon alabosi. * okan ninu awon (omobinrin mejeeji) si so wipe '' ire baba mi, gba (okunrin yi) si ise. Dajudaju eni to dara julo fun o lati gba naa ni, alagbara alafokantan. * O so pe '' mo fe lati fi okan ninu awon omo mi mejeeji yi fun o, pelu mojemu wipe o sise sin mi fun odun mejo; sugbon ti o ba wu o, o le pe odun mewa. Mi o fe lati fi ara ni o, o si ri pe ninu awon eniyan daadaa ni mo wa. * (Anobi Musa) si dahun wipe '' eleyi ni adehun laarin emi ati iwo, Eyikeyi ti mo ba se ninu mejeeji ko ni si abosi nibe lori mi, olohun ni olufeyinti lori oun ti a so. Q28:23-28.

Salim omo Abd Allah sope oun gbo ti Abd Allah omo Umar omo Khatab so ni igba ti oko Hafso omo Umar ku ni ilu Madina, wipe oun lo si odo Uthman omo Afan pe ki o fe Hafso omo oun, o si dahun wipe oun yoo woye si oro naa. Leyin ojo die o so fun mi pe '' mo ri wipe mi o ni le fe omo naa. Umar so pe mo lo si Abu Bakri olododo mo si so fun pe '' ti o ba fe, ma fi omo mi Hafso fun o, Abu Bakri ko fun mi lesi kankan, inu mi si baje juti igba Uthman lo. Leyin ojo die ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ba mi soro lati fe omo naa, mo si fi fun. Leyin naa ni Abu Bakri pade mi o si so pe '' o jo pe o nbinu simi nigba ti o so pe ki nwa fe Hafso, ti mi o si fesi rara? Umar ni mo dahun pe beeni. Abu Bakri wa sope '' ko si oun ti ko je ki nda o lohun jupe pe ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ti so fun mi pe oun fe fe omo naa, mi o si le ma tu asiri ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba). Ti o ba je pe ko pada fe ni mi o ba fe omo naa (Al-Bukhari).


ITAKOKO YIGI, OWO-ORI ATI AYEYE IGBEYAWO

AWON ORIGUN IGBEYAWO NINU ESIN ISLAM
     Ki oko ati iyawo gba lati fe ara won: Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" لا تنكح الأيم حتى تستأمر ولا تنكح البكر حتى تستأذن " قالوا يا رسول الله : وكيف إذنها ؟ قال :" أن تسكت "
'' a ko gbodo fi adelebo (eni ti oti loko ri) loko titi ti a o fi gba ase lodo re, a ko si gbodo fi omoge loko titi ti ao fi gba iyonda lodo re'' won si beere pe ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) bawo ni ao se gba iyonda lodo re? o si dahun wipe '' ti ko ba ti fesi'' (toripe ti ko ba yonu yoo fesi) (Al-Bukhari).
 Eni ti won je nipa lati fe eni ti ko wu ni eto lati ko oko tabi iyawo naa sile.
 Eleyi ni ibamu si isele Khansai omo Judham (ti o je adelebo) ti baba re fi fun eni ti ko te lorun lati fe. O lo so fun ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba), o si tu awon mejeeji ka. Eleyi je idaabobo molebi ki o ma ba daru lola, bakan naa ki iwa ibaje ma ba di gbajumo laarin awujo, ti toko-tiyawo yoo fi ma se ijamba ati abosi ara won latara ainife ara eni.

     Bakan naa, riri alamojuto (fun obinrin) je majemu pataki ninu awon mojemu nini alaafia igbeyawo: Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" لا نكاح إلا بولي وشاهدي عدل وما كان من نكاح على غير ذلك فهو باطل فإن تشاجروا فالسلطان ولي من لا ولي له "
 '' yigi ko le je siso ayafi pelu (riri) alamojuto ati eleri meji onideede (okunrin) eyikeyi igbeyawo ti ko ba ni awon eleyi ninu je igbeyawo ti ko leto, ti awon alamojuto ba se aigbo-ara-eni ye laarin ara won, olori awujo ni alamojuto eni ti ko ni alamojuto'' (Ibn Hiban).
 Islam gbe eleyi kale lati le so okun ebi ki o ma ba ja, bakan naa, toripe alamojuto kii fi owo yepere mu oro awon ti o wa ni abe ikapa re, ko ni se esa tabi fi owo sii fun won, ayafi eyi ti o ba ri wipe o loore fun won ninu awon oun ti won ba fe dawole. Eyikeyi obinrin ti ko ba ni alamojuto tabi alamojuto re ba koti, olori awujo ni yoo je alamojuto re. ni ibamu si oro ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ti o wa loke. Omo Abas so lori aya Al-Quran ti o sope:
" يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا يَحِلُّ لَكُمْ أَن تَرِثُوا النِّسَاءَ كَرْهًا ۖ وَلَا تَعْضُلُوهُنَّ لِتَذْهَبُوا بِبَعْضِ مَا آتَيْتُمُوهُنَّ إِلَّا أَن يَأْتِينَ بِفَاحِشَةٍ مُّبَيِّنَةٍ ۚ وَعَاشِرُوهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ فَإِن كَرِهْتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰ أَن تَكْرَهُوا شَيْئًا وَيَجْعَلَ اللَّهُ فِيهِ خَيْرًا كَثِيرًا "
 '' eyin onigbagbo ododo ko leto fun yin lati jogun awon obinrin nigba ti ko ba tewon lorun, e ko si gbodo fi ara niwon ki e le ba gba ninu oun (owo-ori) ti e fun won, ayafi ti won ba se ibaje (agbere) ti o foju han gbangba, E ma ba won gbe pelu daadaa. Ti e ba si korira won, oseese ki e korira nkan kan ki olohun si fi oore ti o po si nkan naa'' Q4:19.
 Wipe ti okunrin kan ba ku, awon alamojuto re ni won leto si iyawo re julo. Ti o ba wu awon kan ninu won, won yoo fe obinrin naa. Ti o ba si tun wu won won yoo fi loko toripe awon ni won leto si (obinrin naa) ju awon molebi re lo. Eleyi lo si fa ki olohun so ogba oro yi kale. (Al-Bukhari).

     Nigba ti awon mejeeji ba ti gba lati fe ara won, o di oranyan ki oko se esa oun ti yoo fun iyawo re ti yoo si fi le lowo: Olohun sope:
وَآتُوا النِّسَاءَ صَدُقَاتِهِنَّ نِحْلَةً ۚ فَإِن طِبْنَ لَكُمْ عَن شَيْءٍ مِّنْهُ نَفْسًا فَكُلُوهُ هَنِيئًا مَّرِيئًا
 '' e fun awon obinrin ni owo-ori won ti o je (oranyan) lati okan wa. Sugbon ti won ba wa fun yin pada ninu re lati okan won wa, e gba eto lo je fun yin'' Q4:4.
 Owo-ori gbodo wa ni iwontun wonsi. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" إنَّ من يُمنِ المرأةِ تيسيرُ خِطبتِها وتيسيرُ صداقِها وتيسيرُ رحِمِها "
 '' ninu okunfa alubarika fun obinrin, sise bibasoro ati owo ori re ni irorun, eleyi yoo se okunfa oyun ati bibi re ni irorun'' (Al Mustadrak).
 Ori eleyi ni Umar omo Khatab (olohun ko yonu si) sope:
: ألآ لا تغلوا صدق النساء فإنها لو كانت مكرمة (ممدحة) في الدنيا أو تقوى عند الله لكان أولاكم وأحقكم بها محمد صلى الله عليه وسلم ما أصدق امرأة من نسائه ولا امرأة من بناته أكثر من اثنتي عشرة أوقية. [أوقية: معيار للوزن يعادل 200 غرام]
 '' e ma se aseju nibi owo ori awon obinrin, ti o ba je pe aponle ni wiwon re je laye ni, tabi iberu olohun, eni ti ko ba leto si julo ninu yin ni ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba), Ko fun ikankan ninu awon iyawo re tabi omo re ju aoqiya mejila lo (2400 giramu). (Ibn Hiban). Bakan naa lo je dandan ki a se akiyesi pipe awon mojemu ti oko ati iyawo ba fenu ko le lori. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" أحق الشروط أن توفوا به ما استحللتم به الفروج "
 '' eyi ti o fi nleto si pipe julo ninu awon mojemu oun naa ni eyi ti e fi so abe (awon obinrin yin) di eto'' (Al bukhari).

     Ki idunu ati ayo igbeyawo le kun keke, Islam se sise ayeye ni okan pataki ninu awon ojuse, ti awon ara, ore ati ojulumo yoo wa si be: Eleyi wa lati se afihan wipe awon mejeeji ti di toko taya. Anas (olohun ko yonu si) sope:
قدم عبد الرحمن بن عوف المدينة فآخى النبي بينه وبين سعد بن الربيع الأنصاري فعرض عليه أن يناصفه أهله وماله فقال عبد الرحمن: بارك الله لك في أهلك ومالك دلني على السوق فربح شيئا من أقط وسمن فرآه النبي بعد أيام وعليه وضر من صفرة فقال النبي:" مهيم يا عبد الرحمن؟" قال يا رسول الله: تزوجت امرأة من الأنصار قال:" فما سقت فيها؟" فقال: وزن نواة من ذهب فقال النبي: " أولم ولو بشاة "
 '' abdur Rahaman de si ilu Madina. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si so oun ati Sa'du omo Ar Rabi' di omo iya. Sa'du so fun pe ko je ki awon pin awon iyawo ati dukia oun si meji ni dogbandogba. Abdur Rahaman si dahun wipe '' olohun yoo fi ibukun si awon iyawo re ati owo re. juwe oja fun mi'' o si nta wara gbigbe ati ora eran (ti won fi nse obe). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ri (Abdur Rahaman) leyin igba die, o si ri oripa lofinda zafarani lara re, o si so bayi pe '' ki lo sele ire Abdur Rahaman?'' o si dahun wipe '' ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) mo sese fe obinrin kan ninu awon ara ilu Madina ni'' o bi leere wipe '' elo lo san lowo ori re?'' o si dahun wipe '' dirham meta ati aabo'' ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) wa sope: '' se ayeye re koda ki o pa eran kan '' (Al Bukhari).

 O je dandan fun eni ti won ba pe si ibi ayeye igbeyawo lati lo ayafi ti o ba ni idiwo pataki. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
 " إذا دعي أحدكم إلى الوليمة فليأتها"
 '' ti won ba pe enikookan si ayeye igbeyawo, ko ya lo sibe'' (Al-Bukhari).
 O si se pataki fun eni ti o ba lo ki o se adua fun awon oninawo bayi pe:
:" اللهم اغفر لهم وارحمهم وبارك لهم فيما رزقهم "
 '' olohun forijin won, ki o si kewon, ki o si fi ibukun si oun ti o se fun won'' (Ibn Hiban).
 Ko si se adua fun oko ati aya bakan naa pe:
" بارك الله لك وبارك عليك وجمع بينكما في خير "
'' olohun ko se ibukun fun o, ki o si se ibukun le o lori, ki o si se ibukun laarin eyin mejeeji'' (Al-Mustadrak).
 
     Islam yonda fun awon obinrin laarin ara won lati lu ilu (duffu) ki won si da orin ti ko ni ibaje ati iyapa olohun ninu, lati polongo igbeyawo laarin ara won. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) so fun Aisha (olohun ko yonu si) ni igba ti omobinrin kan ninu awon Ansari lo si ile oko wipe:
:" ياعائشة ما كان معكم لهو؟ فإن الأنصار يعجبهم اللهو"
'' ire Aisha (olohun ko yonu si) se e ko ni se ariya ni? Toripe awon Ansari feran ariya ni ti won'' (Al-Bukhari).

 

 

AWON EKO ALE OJO IGBEYAWO

 O se pataki ki oko iyawo ba iyawo re sere ki o si fara roo pelu awon oro ti yoo mu emi re fa si awujo tuntun ti o de, ti ko si fi ni ri arare loun nikan. Eleyi wa ni ibamu si isesi ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba). Asmau omo Yazeed sope:
" إِنَّي قَيَّنْتُ عائشةَ لرسولِ اللهِ صلَّى اللهُ عليه وسلَّمَ ، ثُمَّ جئتُهُ فدعوتُه لجلْوَتِها ، فجاءَ ، فجلس إلى جنبِها ، فأُتِيَ بعُسِّ لبنٍ ، فشرِبَ ، ثُمَّ ناوَلَها النبيُّ صلَّى اللهُ عليه وسلَّمَ ، فخفضَتْ رأسَها واستحيَتْ ، قالتْ أسماءُ : فانتهرْتُها ، وقلْتُ لها : خذِي مِنْ يدِ النبيِّ صلَّى اللهُ عليه وسلَّمَ ، قالَتْ : فأخذَتْ ، فشرِبَتْ شيئًا ، ثُمَّ قال لها النبيُّ صلَّى اللهُ عليه وسلَّمَ : أَعْطي تِرْبَكِ ، قالتْ أسماءُ : فقلتُ : يا رسولَ اللهِ ! بل خذْهُ فاشربْ منْهُ ثُمَّ ناولْنيه مِنْ يدِكَ ، فأخذَهُ فشرِبَ منْهُ ثُمَّ ناولَنيه ، قالت : فجلَسْتُ ، ثُمَّ وضعْتُهُ على رُكْبَتَيَّ ، ثُمَّ طفِقْتُ أُديرُهُ وأُتْبِعُهُ بشفَتَيَّ لأُصيبَ منْهُ شربَ النبيِّ صلَّى اللهُ عليه وسلَّمَ ، ثُمَّ قال لِنسوَةٍ عندِي : ناوِليهِنَّ ، فقلْنَ : لا نَشْتَهِيه ! فقال صلَّى اللهُ عليه وسلَّمَ : لا تَجْمَعْنَ جوعًا وكذبًا .
 '' mo se Aisha loso fun ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) . Mo si pe ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ki o wa wo oso re, o si wa joko si egbe re. o gbe ife wara dani, o mu nibe o si gbe iyoku fun oun naa, o teriba leni to ntiju. Asmau sope: ''mo se lakin mo si so fun pe '' gba lowo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba), O gba o si mu ninu re. leyin naa ni ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) so fun pe '' gbe fun ore re naa'' Asmau ni mo sope '' gba lowo re, ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba), ki o mu leyin naa ki o wag be fun mi'' o gba, o mu, o si gbe fun mi. Asmau sope: ''mo joko mo si gbe si ori itan mi, mo si yi si ogangan ibi ti ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ti mu, mo si mu nibe. O so fun mi pe ki ngbe fun awon obinrin yoku ti won wa pelu mi, mo si gbe fun won. Won si so pe ko wu awon lati mu! Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si so fun won pe '' e mo da ebi ati iro papo'' (Ahmad).

 ILANA ERE SISE LAARIN TOKO TAYA

Esin Islam ka adamo ibalopo laarin okunrin ati obinrin si oun ti o je dandan lati se ni ibamu si ilana ti o leto. Ni igba ti o si je pe ona kan ti Islam gbe kale lati se isesi naa ni igbeyawo, o fe ki toko taya se awon oun ti yoo mu ibalopo naa ni adun ati arinrin laarin ara won. Jabir (olohun ko yonu si) sope:
كنت أسير على ناضح لي في أخريات الركاب فضربه رسول الله ضربة أو قال فنخسه نخسه قال: فكان بعد ذلك يكون في أول الركاب إلا ما كففته قال: فأتاني رسول الله فقال:" أتبيعنيه بكذا وكذا والله يغفر لك؟" قال: قلت هو لك يا رسول الله قال: فزادني قال:" أتبيعنيه بكذا وكذا والله يغفر لك؟" قال: قلت هو لك يا رسول الله قال سليمان: فلا أدري كم من مرة قال: أتبيعنيه بكذا وكذا ثم قال:" هل تزوجت بعد أبيك؟"قال قلت: نعم قال:" أبكرا أم ثيبا؟" قال: قلت ثيبا قال:" ألا تزوجتها بكرا تلاعبك وتلاعبها وتضاحكك وتضاحكها"
 ''mo je eni ti rankunmi ma ngbeyin awon ero. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) gba rakunmi naa, lati igba yi rakunmi naa bere si ni sare ju awon akegbe re lo, ayafi ti mo ba faa seyin, O sope ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) wa sodo mi o si sope: '' se wa ta rakunmi naa fun mi iye bayi bayi, olohun yoo forijin o? o ni mo sope: '' o ti di tire ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba)'' o tun sope ''se wa ta fun mi ni iye bayi bayi, olohun yoo forijin o?'' o sope: '' o ti tire ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba)'', Sulayman (olohun ko yonu si) sope: oun ko mo iye igba ti o beere wipe '' se wa ta fun mi ni iye bayi bayi'' leyin naa o sope '' nje o ti fe iyawo leyin iku baba re? O ni mo sope bee ni, O si dahun pe '' olomoge tabi adelebo? O ni mo sope adelebo. O si sope: '' ki lo de ti o ko fe olomoge ti yoo le ba o sere ti iwo naa yoo le ba sere, ti yoo le pa o lerin ti iwo naa yoo le pa lerin'' (Al-Bukhari ati Muslim).
 Esin Islam pataki ere sise, idoweke ati ifara-ro–ara-eni laarin loko laya. Eleyi ma nse alekun ife ati ajosepo laarin loko laya. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
 " كل شيء ليس من ذكر الله عز وجل فهو لغو و لهو أو سهو إلا أربع خصال: مشي الرجل بين الغرضين ، و تأديبه فرسه ، و ملاعبته أهله ، و تعلم السباحة "
 Gbogbo oun ti ko ba si ninu iranti olohun ere ati awada ni, ayafi awon nkan merin kan; lilo eniyan lati mu ofa ati oun ti o ta ofa mo, titoju esin, iba iyawo eni sere, ati kiko odo wiwe'' (An nasai).

 Bakan naa ekinni-keji loko laya gbodo moju to imototo ara ati sise oso fun eni keji re. oso ara pataki laarin loko laya, toripe o ma nse alekun ife ati asunmo, ko si ni je ki won ma jinna si ara won. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" ... إن الله جميل يحب الجمال "
'' daju daju olohun rewa, o si feran oun to ba rewa'' (Muslim).
 Aisha (olohun ko yonu si) sope:
كنت أطيب (أعطر) النبي صلى الله عليه وسلم بأطيب ما يجد حتى أجد وبيص (بريق) الطيب في رأسه ولحيته.
 '' mo ma nfi lofinda ti o dara julo lodo mi si ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) lara, de bi wipe mo ma nri imole lofinda naa ni ori ati irungbon re'' (Al-Bukhari).

 Ibn Abas (olohun ko yonu si) sope:
إني لأتزين لامرأتي كما تتزين لي ، وما أحب أن استطف كل حقي الذي لي عليها فتستوجب حقها الذي لها علي ، لأن الله تبارك وتعالى يقول :" ولهن مثل الذي عليهن بالمعروف "
'' mo ma nse oso si iyawo mi gege bi oun naa se ma nse oso si mi, toripe mi o fe ki ngba gbogbo eto mi lodo re, ki nwa ma se eto re ti o ni lori mi. toripe olohun sope: '' won ni lori yin iru awon eto ti e ni lori won''.

ERE SISE IFARA-RO-ARA-ENI ATI IDOWEKE
    NI ORI IBUSUN
 O leto fun oko ati iyawo lati bora sile ni ihoho laarin ara won ki enikinni ati enikeji si je igbadun pelu wiwo ara won, Bahzu omo Hakeem sope: baba baba oun bi ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) wipe:
: يا رسول الله عوراتنا (جمع عورة، وهو ما يجب على الإنسان ستره) ما نأتي منها وما نذر (نترك)؟ قال:" احفظ عورتك إلا من زوجتك أو ما ملكت يمينك" قلت: أرأيت إن كان قوم بعضهم فوق بعض؟ قال: إن استطعت أن لا يراها أحد فلا يرينها" قلت: أرأيت إن كان خاليا؟ قال:" فالله أحق أن يستحيي منه "
'' ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ewo lo leto lati han jade ninu awon ihoho wa? O si da lohun wipe:
 
'' bo ihoho re ayafi lodo iyawo re nikan tabi eru re'' o tun beere pe '' ti awon kan ba wa loke awon miran nko?'' o si da lohun pe '' gbiyanju lati ma je ki enikankan ri ihoho re ninu won'' o tun ni '' ti eniyan ba wa ni oun nikan nko?'' o si da lohun wipe '' olohun lo leti ki a tiju re julo'' (Al-mustadrak).
 
Awon mejeeji ni won ni eto lati je igbadun pelu ara won nibi ibalopo ni eyikeyi ona ti o ba te won lorun ayafi biba ara won lopo lati ile igbe (oju idi). Ibn Abas sope Umar wa si odo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) o si sope:
فقال: هلكت قال:" وما أهلكك؟" قال: حولت رحلي الليلة قال: فلم يرد عليه شيئا فأوحى الله إلى رسول الله هذه الآية: " نِسَاؤُكُمْ حَرْثٌ لَكُمْ فَأْتُوا حَرْثَكُمْ أَنَّى شِئْتُمْ " يقول:" اقبل وأدبر واتق الدبر والحيضة"
'' mo ti parun'' ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si dahun wipe: '' ki lo de?'' o dahun pe '' mo ba iyawo lopo lati eyin'' sugbon ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ko so nkankan. Leyin naa ni olohun so oro kale wipe '' awon iyawo yin ogba oko ni won je fun yin e wo ogba oko yin (a ba awon iyawo yin lopo lona to ba wu yin) bi e ba se fe'' Q2:223.
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si sope '' lati iwaju tabi lati eyin, e ko gbodo ba won lopo lati oju idi tabi ni asiko ti won nse nkan osu'' (Ibn Hiban).

 Hadith yi ko toka lori wipe a gbodo jinna si obinrin ti nse nkan osu tabi pe a ko gbodo jeun pelu re tabi mu omi pelu re. Aisha (olohun ko yonu si) sope:
فعن عائشة قالت: كنت أشرب وأنا حائض ثم أناوله النبي صلى الله عليه وسلم فيضع فاه على موضع في فيشرب وأتعرق العرق وأنا حائض ثم أناوله النبي صلى الله عليه وسلم فيضع فاه على موضع في.
 '' mo ma nmu omi ti maa si gbe fun ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ni asiko ti mo ba nse nkan osu lowo, ti yoo si mu omi naa ni ogangan ibi ti mo ti mu, mo ma nfenu gee ran je ni asiko ti mo nse nkan osu lowo ti ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) yoo si gba eran naa ti yoo si ge je ni ogangan enu mi'' (Muslim).

 Bakan naa kii se eewo ki oko ati iyawo je igbadun ara won ni asiko ti obinrin nse nkan osu lowo. Anas sope:
 فعن أنس أن اليهود كانوا إذا حاضت المرأة فيهم لم يؤاكلوها ولم يجامعوهن في البيوت فسأل أصحاب النبي النبي فأنزل الله تعالى " ويسألونك عن المحيض قل هو أذى فاعتزلوا النساء في المحيض إلى آخر الآية فقال رسول الله :"اصنعوا كل شيء إلا النكاح" فبلغ ذلك اليهود فقالوا: ما يريد هذا الرجل أن يدع من أمرنا شيئا إلا خالفنا فيه فجاء أسيد بن حضير وعباد بن بشر فقالا يا رسول الله: إن اليهود تقول كذا وكذا فلا [ أفلا ؟ ؟ ] نجامعهن؟ (أي: إنَّ اليَهُودَ لا يُجامِعون النِّساءَ في وقتِ الحَيْض؛ أفلا نُخالِفُهم ونُجامِعُهُنَّ؟) فتغير وجه رسول الله حتى ظننا أن قد وجد عليهما فخرجا فاستقبلهما هدية من لبن إلى النبي فأرسل في آثارهما فسقاهما فعرفا أن لم يجد عليهما.
 '' awon Yehuudi kii ba obinrin jeun ni asiko ti o ba nse nkan osu lowo bakan naa ni won kii ba won gbe inu ile papo lasiko yi. Awon omoleyin ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) beere nipa eleyi lowo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba), Olohun so oro re kale pe:
وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْمَحِيضِ ۖ قُلْ هُوَ أَذًى فَاعْتَزِلُوا النِّسَاءَ فِي الْمَحِيضِ ۖ وَلَا تَقْرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطْهُرْنَ ۖ فَإِذَا تَطَهَّرْنَ فَأْتُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ أَمَرَكُمُ اللَّهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ التَّوَّابِينَ وَيُحِبُّ الْمُتَطَهِّرِينَ "
 '' won yoo ma bi e leere nipa nkan osu, sope egbin ni (ki oko ba iyawo re lopo ni asiko yi), fun idi eyi, e jinna si awon obinrin ni asiko nkan osu. E ma se sun mo won (ba won lopo) titi ti won yoo se mora. Ti won ba ti se imora e sun mo won (ba won lopo) lati aye ti olohun payin lase re. olohun feran awon ti o ma nronu piwada o si feran awon olu se imora'' Q2:222. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si sope '' e se gbogbo nkan (pelu awon iyawo yin) ayafi ibalopo''.

Nigba ti awon Yehuui gbo eleyi won sope '' okunrin yi sa feran lati yapa wa ninu gbogbo nkan''. Asyad omo Khudairi ati Abbad omo Bashar sope: '' ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) awon Yehuudi nso bayi bayi, se aa ni ma ba awon iyawo lopo ni asiko yi bi? (toripe awon Yehuudi won kii ba awon iyawo won lopo ni asiko yi, lati fi yapa won), oju ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) yi pada, won si rope o nbinu si awon ni, awon mejeeji si jade. Won gbe ebun wara ti won ngbe bowa fun ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) pade won, ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si ni ki won lo fun awon mejeeji nibe. Won mu wara naa won si ri wipe ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ko binu si awon'' (Muslim).
 
 Jabir omo Abd Allah (olohun ko yonu si) sope:
قالت: اليهود إن الرجل إذا أتى امرأته وهي مجبية جاء ولده أحول فنزلت (نساؤكم حرث لكم فأتوا حرثكم أنى شئتم البقرة) إن شاء مجبية وإن شاء غير مجبية إذا كان في صمام واحد.
 '' awon Yehuudi ma nsope ti okunrin ba ba iyawo ni ibalopo ni igba ti obinrin ba wa ni idojubole (ni oju ara sugbon lati eyin), yoo bi omo ti oju re da. Ni oro olohun ba so kale pe '' awon iyawo yin ogba oko ni won je fun yin. E wo ogba oko yin (e ba won ni ibalopo) bi e ba se fe''. Ti o ba wu ki o ba lopo ni idojubole, ti o ba si tun wu ki o ba lopo nigba ti (obinrin) ko dojubole, ki o sa ti wo aaye ti o ye (oju ara).

 Ninu sunnah ni ki won daruko olohun siwaju ki won to ni ibalopo. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" لو أن أحدهم إذا أراد أن يأتي أهله قال باسم الله اللهم جنبنا الشيطان وجنب الشيطان ما رزقتنا فإنه إن يقدر بينهما ولد في ذلك لم يضره شيطان أبدا "
 '' ni igba ti enikookan yin ba fe ba iyawo re lopo, ki o so pe ''pelu oruko olohun, ire olohun gbe esu jinna si wa, ki o si gbe esu jinna si oun ti o se fun wa'' ti olohun ba ko omo mowon nibi ibalopo naa, esu ko ni ko inira ba lailai'' (Al Bukhari).

 Bakan naa oko gbodo ba iyawo re sere daradara, ki o fi enu ko lenu, ki o si fi owo ra lara, lati je ki ara re gbe si ibalopo, ki o si je ki (obinrin) naa setan ki o to dide lori re.

 Beeni ti okunrin ba gbero lati se ju eekan lo, ninu sunnah ni ki o we iwe janabah tabi ki o se aluwala ki o to se eleekeji. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
 
" إذا أتى أحدكم أهله ثم أراد أن يعود فليتوضأ "

 '' ti enikookan ninu yin ba ba iyawo re ni ibalopo, ti o wa gbero lati se si, ki o ya se aluwala'' (Muslim).
 Eleyi je imototo atipe o ma nfunni ni agbara lati ni ibalopo daradara.

    NI ILE IWE
 Ere sise, idoweke ati ifara-ro-ara-eni laarin loko laya ko mo si ori ibusun ati asiko ibalopo nikan. O leto ki won se isesi yi ni gbogbo aaye, ni iwonba igba ti awon eniyan ba jinna si won, ti won si ni ma ri won tabi gbo ohun won. Aisha (olohun ko yonu si) sope:
 
فعن عائشة رضي الله عنها قالت : كُنتُ أغتسلُ أَنا ورسولُ اللَّهِ صلَّى اللَّهُ علَيهِ وسلَّمَ من إناءِ واحدٍ ، يبادِرُني وأبادرُهُ ، حتَّى يقولَ : دَعي لي وأقولُ أَنا : دَع لي.
'' mo ma nwe pelu ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ninu abo omi kan naa, a o si jo ma se fanfan lori omi (ni ti idoweke), titi ti yoo fi so fun mi pe '' fi (omi) sile fun mi. emi naa o si so pe '' fi (omi) sile fun mi'' (An-nasai).

    NI INU ILE
 Shuraeh omo Hani beere lowa Aisha (olohun ko yonu si won) wipe:
سأل شريح بن هانئ عائشة أم المؤمنين رضي الله عنها فقال: "بأيِّ شيءٍ كان يبدأُ النبيُّ صلَّى اللهُ عليهِ وسلَّمَ إذا دخل بيتَهُ ؟ قالتْ : بالسواكِ
 '' kinni ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ma nkoko se ti o ba wole? O si dahun pe '' pako rirun'' (Muslim).
 Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) feran lati ma pade awon ara ile re ni eni ti o wa ni imototo.

    NI ITA GBANGBA
 Mojemu eleyi ni wipe won gbodo jinna si awon elomiran, ti won ko fi ni ma riwon tabi gbo ohun won, Abu Salamah omo Abdur Rahaman sope:
أخبرتني عائشة أنها كانت مع رسول الله في سفر وهي جارية (فتاة) فقال لأصحابه:" تقدموا ثم قال: تعالي أسابقك" فسابقته فسبقته على رجلي فلما كان بعد خرجت معه في سفر فقال لأصحابه:" تقدموا ثم قال: تعالي أسابقك" ونسيت الذي كان وقد حملت اللحم فقلت: كيف أسابقك يا رسول الله وأنا على هذه الحال فقال:" لتفعلن" فسابقته فسبقني فقال:" هذه بتلك السبقة "
 '' Aisha (olohun ko yonu si won) so fun mi pe oun wa pelu ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ni irin ajo. Oun si je olomoge. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) so fun awon omoleyin pe '' e rin sunmo iwaju'' o si so fun mi pe '' bo si bi, je ka jo sare ije'' a jo sare ije mo si siwaju re. A tun jo se irin ajo miran. O si tun so fun awon omoleyin wipe '' e rin sunmo iwaju'' o si so fun mi wipe '' bo sibi ka jo sare ije'' mo ti gbagbe ti akoko bakan naa mo ti sanra si. Mo wa sope ire ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) bawo ni mo se fe sare ije pelu re pelu bi mo se wa yi? O si dahun wipe '' o gbodo sa ni'' a ba jo sa ere naa, o si siwaju mi. o wa sope '' fi eleyi di ti akoko'' (Asunanu-l-kubra).

 A gbodo mo wipe eewo lo je fun eyikeyi ninu oko ati iyawo lati ma so isesi tabi asiri ibalopo laarin won jade, tabi ki o so di oro awada laarin oun ati awon ore re. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba):
" إن من أشر الناس عند الله منزلة يوم القيامة الرجل يفضي (يخلو بها) إلى امرأته وتفضي إليه ثم ينشر أحدهما سر صاحبه "
'' ninu awon ti aaye won yoo buru julo lodo olohun ni ojo igbende, ni arakunri ti o wa ni ikoko pelu iyawo re (fun ibalopo) ti obinrin naa si pamo pelu re, ti okan ninu won wa ntu asiri enikeji re sita'' (Muslim).

 Ki ajosepo ti o gunrege le wa laarin toko taya, ati ki won si le gbe ile esin ti o la kuro nibi ija, eebu, wahala ati ikunsinu. Ofin Islam salaye ojuse ti enikinni gbodo se fun enikeji ati iwo onikaluku lodo ara won.
 

NINU AWON IWO IYAWO LORI OKO RE

 Die ninu awon ojuse ti oko ni lati pe fun iyawo re niwonyi ni ibamu si oro olohun ati ti ojise re (ike ati ola olohun ko moo ba)
 
1.    Olohun sope:
وَعَاشِرُوهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ فَإِن كَرِهْتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰ أَن تَكْرَهُوا شَيْئًا وَيَجْعَلَ اللَّهُ فِيهِ خَيْرًا كَثِيرًا"
 '' e ba won gbepo pelu daadaa. Ti e ba korira won, o seese ki e korira nkankan ki olohun si fi oore ti o po si (nkan naa)'' Q4:19.

2.    Olohun sope:
وَلَهُنَّ مِثْلُ الَّذِي عَلَيْهِنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ وَلِلرِّجَالِ عَلَيْهِنَّ دَرَجَةٌ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
 '' awon naa ni (lodo awon oko won) iru awon iwo ti (awon oko) won ni lori won, ni ti deede. Atipe awon okunrin ni ajulo lori won, Olohun ni oba abiyi ojogbon'' Q2:228.

3.    Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" خيركم خيركم لأهله وأنا خيركم لأهلي "
 '' eni to loore julo ninu yin ni eni to dara julo si ara ile re'' (Ibn Majah).

4.    Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" أكمل المؤمنين إيمانا أحسنهم خلقا وخياركم خياركم لنسائهم "
 '' eni ti igbagbo re pe julo ninu awon onigbagbo ododo ni eni ti iwa re dara julo ninu won, atipe awon ti won loore julo ninu yin ni awon ti won dara julo si awon obinrin won'' (Ibn Majah).

5.    Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
"فاتقوا الله في النساء فإنكم أخذتموهن بأمان الله واستحللتم فروجهن بكلمة الله"
 '' …e beru olohun lara awon obinrin, toripe e mu won pelu adehun olohun, e si so abe won di eto pelu oro olohun….'' (Muslim).

6.    Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" لا يفرك (يبغض) مؤمن مؤمنة إن كره منها خلقا رضى منها آخر أو قال غيره"
 '' ki onigbagbo ododo lokunrin (oko) ma se korira onigbagbo ododo lobinrin (iyawo), ti o ba korira iwa kan lara re yoo ri omiran ti yoo yo ninu'' (Muslim).

7.    Hakeem omo Maa'wiya gbo lati odo baba re pe oun beere lowo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) wipe '' kin ni awon eto ti awon iyawo wa ni lori wa?'' ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si dahun pe:
" أن تطعمها إذا طعمت وتكسوها إذا اكتسيت أو اكتسبت"
 '' ki o ma fun lounje ti iwo ba ti njeun, ki o si ma fun laso wo ti iwo naa ba ti nwo aso'' (Abu Dawud).

 

NINU AWON IWO TI OKO NI LORI IYAWO RE

 Die ninu awon iwo ti oko ni lori iyawo re niwonyi ni ibamu si oro olohun ati ojise re (ike ati ola olohun ko moo ba).

1.    Olohun so nigba ti o nroyin awon obinrin rere wipe:
 " فَالصَّالِحَاتُ قَانِتَاتٌ حَافِظَاتٌ لِّلْغَيْبِ بِمَا حَفِظَ اللَّهُ
 '' awon obinrin rere, (ni) awon ti won ntele ase awon oko won, ti won si nso (abe won ati dukia oko) ni igba ti oko won ko ba si nile, oun ti olohun ni ki won so'' Q4:34.

2.    Husoin omo Muhson (olohun ko yonu si) sope:
حدثتني عمتي قالت : أتيت رسول الله صلى الله عليه وسلم في بعض الحاجة ، قال :" أي هذه أذات بعل أنت (هل لك زوج) ؟ " قلت: نعم ، قال :" كيف أنت له ؟ " قالت : ما ألوه (أي لا أقصر في طاعته وخدمته وأداء حقه) إلا ماعجزت عنه، قال :" فأين أنت منه فإنما هو جنتك ونارك" ("جنتك ونارك" : أى إن الزوج هو سبب لدخولك الجنة برضاه عنك ، وسبب لدخولك النار بسخطه عليك فأحسنى عشرته)
 '' omo iya baba mi lobinrin sope '' mo lo si odo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) fun awon bukata kan'', o si sope '' nje o loko bi?'' mo ni beeni. O beere wipe '' bawo lo se ri si oko re? mo dahun pe '' mi o se aseeto nibi titele ase re, itoju re ati pipe iwo re fun, ayafi oun ti mi ko ba ni ikapa re, o wa dahun wipe '' boba se wu ko je, oun ni (okunfa wiwo) ogba idera re(nigba ti o ba nyonu si o) ati ina re(nigba ti o ba nbinu si o)'' (Al mutadrak).

3.    Abu Huraira (olohun ko yonu si) sope ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
قال رسول الله صلى الله عليه وسلم :"إذا صلت المرأة خمسها وصامت شهرها وحصنت فرجها وأطاعت بعلها دخلت من أي أبواب الجنة شاءت"
 '' ti obinrin ba ki irun wakati marun re perepere, ti o si gba awe Ramadan, ti o si so abe re, ti o si tele ase oko re, yoo wo ogba idera lati ibi eyikeyi ilekun ogba idera ti o ba fe'' (Ibn Hiban).

4.    Maa'dh omo Jabal (olohun ko yonu si) sope:
عن معاذ بن جبل رضي الله عنه أنه أتى الشام فرأى النصارى يسجدون لأساقفتهم وقسيسيهم وبطارقتهم ورأى اليهود يسجدون لأحبارهم ورهبانهم وربانيهم وعلمائهم وفقهائهم فقال: لأي شيء تفعلون هذا قالوا: هذه تحية الأنبياء عليهم الصلاة والسلام قلت: فنحن أحق أن نصنع بنبينا فقال نبي الله صلى الله عليه وسلم:"إنهم كذبوا على أنبيائهم كما حرفوا كتابهم لو أمرت أحدا أن يسجد لأحد لأمرت المرأة أن تسجد لزوجها من عظيم حقه عليها ولا تجد امرأة حلاوة الإيمان حتى تؤدي حق زوجها ولو سألها نفسها وهي على ظهر قتب"  
 ''oun wa si ilu Shamu, oun si ri awon elesin kirisiteni ti won nfori bale fun awon asiwaju, asiwaju ati onimimo won, oun si ri awon Yehuudi ti won nfori bale fun awon alufa, olujosin, olureni, onimimo ati awon agba alufa won. O wa sope '' ki lo de ti e fi nse eleyi? Won si dahun wipe '' eleyi ni ilanan ikini fun awon anabi olohun (ike ati ola ki o ma ba won). Mo sope: '' awa ni a leto julo lati se eleyi fun anabi wa (ike ati ola olohun ko ma ba). Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) fesi pe '' dajudaju iro ni won pa mo awon anabi olohun, gegebi won se yi iwe won pada. Ti o ba jepe ma pa enika lase ki o fi ori bale fun elomiran, obinrin ni mi o ba pa lase ki o fori bale fun oko re, latara bi iwo re (oko) se tobi to lori re. obinrin Kankan koni to adun igbagbo wo ayafi igba ti o ba to pe iwo oko re, koda ko beere fun lati ba lopo lori eyin rakunmi''(Al Mustadrak).


IKORA ENI SILE NINU ISLAM

Igbeyawo je oun owo ninu esin Islam, Idi niyi ti esin Islam fi ni akolekan lori gbogbo oun ti yoo ba se okunfa ajosepo ti o yanju ti o si fidi mule laarin loko laya. Ninu awon oun ti o ntoka lori wipe oun owo ni igbeyawo je ni oro olohun ti o fi pe igbeyawo ni '' adehun ti o yi (ni agbara).
وَأَخَذْنَ مِنكُم مِّيثَاقًا غَلِيظًا " "
 '' won si gba adehun ti o yi lowo yin'' Q4:21.
 Bakan naa ni oro ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ti o sope:
" من خبب (خدع وأفسد) زوجة امرئ أو مملوكه فليس منا ومن حلف بالأمانة فليس منا "
 '' enikeni ti o ba ko ibaje tabi itanje ba iyawo tabi eru elomiran, ko si lara wa. Eni to ba si bura (iro) lori gbafipamo kii se ara wa'' (Ibn Hiban).

 Pelu bi Islam se pataki igbeyawo to yi, bakan naa ni o se ikora eni sile leto, nigba ti igbesiaye ko ba lojutu mo laarin awon mejeeji, leyin igba ti won ba ti lo gbogbo ona ti o ye lati wa atunse si aarin won sugbon ti ko yanju, Eleyi je ilanan lati denan ijanba laarin loko laya, ki o ma ba di pe omo ale yoo wo inu molebi, ti eni ti ko leto si ogun yoo ma jogun, ti eni to leto si yoo si padanu re, ti iwa agbere yoo si di gbajumo. Nigba ti ile ba ti padanu ife lati re omo ni ona ti o dara latari wahala ati ijangbon laarin loko laya, adanwo ni yoo mu wa fun awujo.


MOJEMU IKORA ENI SILE NINU ISLAM

Ikora eni sile ninu esin Islam ni awon mojemu ti o je oranyan lati se akiyesi re ki o to waye. Bakan naa ni pe o ni awon idajo orisirisi ni asiko otooto:

1)    A ma bosi ipo oranyan nigbati awon ojogbon meji ba dajo tituka laarin won, nigba ti aarin won ko ba gun mo rara. Olohun sope:
" وَإِنْ خِفْتُمْ شِقَاقَ بَيْنِهِمَا فَابْعَثُوا حَكَمًا مِنْ أَهْلِهِ وَحَكَمًا مِنْ أَهْلِهَا إِنْ يُرِيدَا إِصْلَاحًا يُوَفِّقِ اللَّهُ بَيْنَهُمَا إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا خَبِيرًا
 '' ti e ba npaya idaru dapo laarin awon mejeeji (toko taya) e gbe ojogbon dide ninu awon molebi re (oko) ati ojogbon ninu ebi (iyawo) re. ti won ba gbero atunse olohun yoo so (emi) won po, dajudaju olohun ni onimimo olu funni niro (oun ti a se)'' Q4:35.

2)    A si ma je eewo nigba ti ko ba si okunfa tabi idi kan pataki ti o le fa ikora eni sile. Eleyi je okan ninu awon ise esu tio ma nse laarin loko laya. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
" إن أبليس يضع عرشه على الماء ثم يبعث سراياه ، فأدناهم منه منزلة أعظمهم فتنة ، يجيء أحدهم فيقول فعلت كذا وكذا ، فيقول : ماصنعت شيئاً ، قال : ثم يجيء أحدهم فيقول : ما تركته حتى فرقت بينه وبين إمرأته ، قال : فيدنيه منه ويقول : نعم أنت "
'' esu ma ngbe aga re si ori omi (okun), o si ma nran awon omo leyin re jade lo, eni ti yoo je alasunmo julo si esu ninu won ni eni ti adanwo re ba poju (nibi siso awon eniyan nu kuro nibi eto ati ododo), eni akoko yoo de ninu won yoo si wipe mo se bayi bayi. Esu yoo si dahun wipe '' o se nkankan'' enikeji yoo si dahun pe ''mo gbiyanju titi ti mo fi se opinya laarin oun ati iyawo re'' esu yoo wa sope '' sun mo biyi iwo ni eni naa'' (Muslim).

3)    A si ma wa lori fife oko nigba ti iyawo ba je oni iwa buruku si oko re. bi o tile jepe o dara ki oko se suuru, pataki julo nigba ti omo ba ti wa laarin won.

4)    A si ma nje dandan nigba ti iyawo ba je eni ti kii tele awon ofin ati ilana esin. Tabi ti o ba je alagbere ti ko gba waasi. Eleyi je eto oko nigba ti okan ninu awonnkan wonyi ba sele. Bakan naa ti iyawo ba je eni ti ko se ba se ibalopo tabi ko feran sise asepo rara ti eleyi si je inira nla fun oko.


(AL KHUL'U') KI OBINRIN BEERE FUN IKOSILE LOWO OKO RE

 Nigba ti igbe aye loko laya ko ba si lori ife, ti o si agboye ati ibagbepo daadaa mo, ti igbeyawo di inira, ifooro ati adanwo, pataki julo nigba ti okan ninu awon mejeeji ba korira enikeji re. Islam fe ki a se suuru ati ifarada niru asiko yi olohun sope:
فَإِن كَرِهْتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰ أَن تَكْرَهُوا شَيْئًا وَيَجْعَلَ اللَّهُ فِيهِ خَيْرًا كَثِيرًا
'' ti e ba korira won, o seese ki e korira nkankan ki olohun si fi oore ti o po si'' Q4:19.

 Sugbon ti oro ba koja suuru ati ifarada laarin awon mejeeji. Nigbayi ni okan ninu الطلاق" '' At tolaq yoo sele ti ikorira iyawo ba wa lati odo oko, tabi '' الخلع '' Al khul'u' nigba ti ikorira ba wa lati odo iyawo. Itumo Al khulu' ni pe obinrin yoo da owo ori ti oko re fun pada lati yo ara re kuro ni ipo iyawo fun okunrin naa. Eleyi je ilana deede ti Islam gbe kale. Toripe oko lo san owo ori oun naa si ni o ngbo bukata loko laya laarin awon mejeeji. Olohun sope:
" وَلَا يَحِلُّ لَكُمْ أَن تَأْخُذُوا مِمَّا آتَيْتُمُوهُنَّ شَيْئًا إِلَّا أَن يَخَافَا أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ اللَّهِ ۖ فَإِنْ خِفْتُمْ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ اللَّهِ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَا فِيمَا افْتَدَتْ بِهِ ۗ "
 '' ko leto fun yin lati gba nkankan ninu oun (owo ori) ti e fun won, ayafi ti won (oko ati iyawo) ba npaya pe awon ko ni le duro lenu aala olohun. Ti e ba wa npaya pe won (oko ati iyawo) ko ni le duro lenu aala olohun, ko si ese fun eyikeyi ninu awon mejeeji lori oun ti (obinrin) ba fi sile (owo ori ti o gba) Q2:229.

 Ibnu Abas gba wa pe Jameelah omo Saluul wa si odo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) o si sope:
واللَّهِ ما أعتِبُ علَى ثابتٍ في دينٍ ، ولا خُلقٍ ، ولَكِنِّي أكْرَهُ الكُفرَ في الإسلامِ ، لا أطيقُهُ بُغضًا ، فقالَ لَها النَّبيُّ صلَّى اللَّهُ علَيهِ وسلَّمَ : أترُدِّينَ علَيهِ حديقتَهُ ؟ قالَت : نعم ، فأمرَهُ رسولُ اللَّهِ صلَّى اللَّهُ علَيهِ وسلَّمَ أن يأخذَ منها حديقتَهُ ، ولا يزدادَ.
'' mi o korira Thabit latari esin tabi ije omoluwabi re, sugbon mo korira ki nse keferi (aimoore si oko mi nibi ife tabi sise dada si) ninu Islam. Mi o le duro fara da mo latari ikorira. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si so fun pe '' se wa da ogba oko re pada fun? O si dahun wipe '' beeni'' ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si pa lase ko gba ogba oko re pada lowo re, ko si ma lekun'' (Ibn Majah).

 Idi ti Islam fi yonda eleyi ni lati so iyi ati aponle omoniyan kuro nibi idoti ati iyepere, bakan naa lati dena gbogbo oun ti o ba le fa iwa ibaje si awujo. Toripe ki okunrin tabi obinrin ma wa pelu eni ti ko nife le fa iwa agbere, eyi ti o je eewo, pataki julo nigba ti ko ba si eko esin ati iberu olohun ti o lagbara, Eleyi lo si fa ti ikora eni sile fi leto. olohun sope:
وَإِن يَتَفَرَّقَا يُغْنِ اللَّهُ كُلًّا مِّن سَعَتِهِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ وَاسِعًا حَكِيمًا
'' ti won ba tuka (ko ara won sile) olohun yoo ro enikookan won loro ninu opo (ola) re. olohun je eni to gbaaye ojogbon'' Q4:130.


AWON ABAYO ABURU TI O WA FUN IWA AGBERE (ZINA)

Islam se iwa agbere ni eewo. O je okan ninu awon ese nla. Bakan naa, eewo ni gbogbo oun ti o ba le je okunfa fun iwa agbere. Sayid Qutub sope: '' islam wa lati gbogun ti isesi eranko, eyi ti kii se opinya laarin eto ati eewo, laarin omoniyan. Islam gbe ilanan kale lati gbe ile ati awujo ti o dara duro. Bakan naa lati fi ipile ajose lailai lele laarin okunrin ati obinrin gegebi oko ati aya. Islam se leto lati fi ibagbepo ti o ni owo ati aponle ninu lele nibi didapo emi, okan ati ara omoniyan meji ni eyi tii se ti eranko. Eleyi ti yoo so awon mejeeji di eni won yoo jo ma gbe papo, ti won yoo jo ma ronu papo, ti won yoo si jo ma ni iwoye ojo ola papo. Bakan naa ti awon omo daadaa yoo si ti ara won jade, ti won yoo bi iran tuntun ti yoo dagba soke lori daadaa ati idagbasoke awujo.

Eleyi lo fa ti islam fi gbe iya ti o le kale lori agbere sise. Bakan naa o je iwa eranko ti ko ni je ki daadaa sele ni awujo, ti yoo si tun dena idagbasoke awujo, ti yoo si je ki omoniyan pada si isesi eranko ninu aworan omoniyan. Islam ko tako awon adamo omoniyan sugbon o wa lati gbe awon ilanan ti yoo je ki o wa lori bi o se to ati bi o se ye kale, Iwa agbere tabi ise asewo ma nyo omoniyan kuro ni ipo omoluwabi lo si ipo eranko, ti yoo si so di eni yepere ti o tun buru ju eranko lo.

DIE NINU AWON ABAYO ABURU TI O WA NIBI IWA AGBERE

Siseyo awon aisan ati ajakale arun ti ko si tele, ti kii si mo lori alagbere nikan. Olohun sope:
وَلَا تَقْرَبُوا الزِّنَا ۖ إِنَّهُ كَانَ فَاحِشَةً وَسَاءَ سَبِيلًا
'' e ma se sunmo agbere dajudaju ibaje ni, oju ona aburu si ni'' Q17:32. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" ...يا معشر المهاجرين خمس إن ابتليتم بهن ونزل فيكم أعوذ بالله أن تدركوهن لم تظهر الفاحشة في قوم قط حتى يعملوا بها إلا ظهر فيهم الطاعون والأوجاع التي لم تكن مضت في أسلافهم.
 ' eyin Muhajirun, awon nkan marun kan, ti won ba fi won se adanwo fun yin, mo fi olohun waso nibi ko sele loju yin. Agbere ko ni seyo ni awujo kan, ti awon eniyan si nse, ayafi ki igbona ati ajakale arun, ti won ko gbo ri lodo awon baba won, sele si won…'' (Al mustadrak).

 Iwa agbere ma nmu ewa oju kuro, toripe enikan ko ni se isesi yi ayafi eni ti emi re doti, ti ko si yato ni isesi ti eranko. Bakan naa o ma nfa osi ati aini. Latari owo, igbiyanju ati asiko ti awon alagbere ma nna lori re, o si ma nfa abamo ni aye ati iya ti o le koko ni orun. Bakan naa o ma nfa kukuru emi latari kikoba alaafia ara ati awon aisan orisirisi ti o ma ntibe jade.

 Pipo omo ale (ti ko ni baba) lawujo: Ni opolopo igba ni won kii ri olutoju ti yoo dari ese won sibi dada ti aye ati ti orun. Ise obi ni ki o moju to omo ti elomiran ko si le ba se bo se to ati bi o se ye, Awon ijo ati ile omo alainiya se afirinle awon wahala ti awon ma nkoju lati se aseyori lori ikookan ti awon ni aseyori lori won ninu iru awon omo bayi.
 
 Fifanka awon aisan ati aibale emi ti o ma nbe fun awon alagbere. Olohun sope:
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِّتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
 '' ninu awon amin olohun ni pe o da fun yin latara yin awon iyawo yin, ki e le fokanbale sodo won, o si se ife ati ike si aarin yin. Amin nbe ninu eleyi fun awon ti o le ronu'' Q30:21.

 O ma nse okunfa awon iwa buruku miran. Nigba ti alagbere ko ba lowo lati se aburu re yi, yoo wa ona miran lati ri owo tabi lati ri oun ti o fe se ni onankonan.

 O ma nse okunfa siso kale iya olohun lori awujo ti iru buruku yi ba ti nwaye. Ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sope:
:" لا تزال أمتي بخير ما لم يفش فيهم ولد الزنا فإذا فشا فيهم ولد الزنا فيوشك ان يعمهم الله عز وجل بعقاب"
'' awon ijo mi ko ni ye ma be lori daadaa, nigba ti omo ale ko ba ti fonka laarin won, ti omo ale ba ti fonka laarin won, yoo ku die ki iya olohun bo won daru'' (ahmad).


ORO IPARI:

Eleyi ni die nipa iwoye ati itoka esin islam si ibani lopo larin okunrin ati obinrin, eyiti an ngbero pelu re wipe koje okunfa imona fun eniti to ngbero a'lekun mimo nipa agborin yii ati ona ti islam gba lati se atunse re ki ole mu di ijosin eyiti musulumi yio gba esan dada ati laada lori ti oba se pelu ofin ati ilana ti islam fi lele lori re. Bakanna la ngbero pelu re wipe koje okunfa inife si alekun mimo nipa esin isla, esin to sinu gbogbo alamori omoniyan yala nipa ibalopo re pelu elomiran tabi nipa awon alamori esimi re pelu awon arale re nikan tabi awon oun toni se pelu re leyin iku re, toripe islam fi rinle pe esan ise dada ti omoniyan ba fi le leyin iku yio moba, bakanna pe yio si moo lobe nigbakigba ti dada naa ba, ojise olohun- ki ike ati ige olohun ko mob a sope:
إذا مات الإنسان انقطع عنه عمله إلا من ثلاثة إلا من صدقة جارية أو علم ينتفع به أو ولد صالح يدعو له"
" ti omoniyan baku gbogbo ise re ni yio duro ayafi nkan meta; sara to nsan to fiile abi imo kan to fii sile ti won san faani pelu re tabi omo re to fi saye to n sa dua fun"

Ati oro ojise olohun to sope:
من دعا إلى هدى كان له من الأجر مثل أجور من تبعه لا ينقص ذلك من أجورهم شيئا ومن دعا إلى ضلالة كان عليه من الإثم مثل آثام من تبعه لا ينقص ذلك من آثامهم شيئا"
" enikeni to ba pepe si dada kan yio gba esan dada gegebi eni to tele nibi dada naa, eleyi koni din esan won ku, bakanna eniti oba pepe si iburu kan, yio gba esan iburu gegebi esan eniti o tele ni ni aburu naa, eleyi kosi ni din esan aburu won ku"
Lara ohun to n toka si ikotan islam ni ikolekan re si awon isesi eyi to niise pelu isemi omoniyan; Salman sope: awon olusi ebo so fun wa pe: awa ri ore yi leni ti ko yin leko debi pe o nko yin leko ba se nse igbonse…" Muslim lo gba wa.

Esin nla leleyi, esin to dara pupo niyii, esin toda si gbogbo alamori ati isesi omoniyan, esin toto isemi aye omoniyan. Owa ye fun awa musulumi kadimo esin yin bose ye ati bo seto, ki asi mope awon eniyan si inu oore esin yii ki awon naa le gbadun oore re. Bakanna oje ohun Pataki fun awon elesin mi naa ki won mo nipa esin ati paapa re pelu ki won gbe ji naa si okan won eyameya esin ki won le moa won ola ati paapa esin islam. Esin islam je esin to npepe si gbogbo daada, to si n danamo gbogbo aburu.

 


 
www.islamland.com