MUHAMMAD: OJISE OLOHUN (IKE ATI OLA OLOHUN KO MO BA)

MUHAMMAD: OJISE OLOHUN (IKE ATI OLA OLOHUN KO MO BA)

MUHAMMAD: OJISE OLOHUN
(IKE ATI OLA OLOHUN KO MO BA)

محمد رسول الله صلى الله عليه وسلم بلغة اليوروبا


Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
د. عبد الرحمن بن عبد الكريم الشيحة


Itumo ni ede Yoruba
European Islamic Research Center (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Abd Ar-Razzaq Isa
Atunto
Ridwan Allah Murtadho
 

www.islamland.com

 

بسم الله الرحمن الرحيم
Ni oruko olohun oba ajoke aye asake orun
MUHAMMAD: OJISE OLOHUN
(IKE ATI OLA OLOHUN KO MO BA)
     Ope ni fun Olohun adeda ati olutoju gbogbo agbaye, ike ati ola Olohun ki o ma ba Anabi Muhammad (ike ati ola olohun ko moo ba) ati awon ara ile re ati awon omoleyin re lapopo.
ORO ITISIWAJU
     Nigba ti a ba nsoro nipa Muhammad Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ti Olohun ran si gbogbo eniyan, a nsoro nipa eni ti o pataki julo ninu itan omoniyan lakotan. Gbogbo eni ti o ba ka nipa itan Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ko moo ba), ti o si mo awon iwa eleyin ati iroyin ti o ga ti nbe fun, ti o si la kuro nibi gbogbo iran eleyameya, ni yoo jeri wipe oun ni eni abiyi ati eni pataki julo ninu eda omoniyan. Koda awon olukowe ti kii se elesin islam jeri si oun ti a so yi.
      Amoye Hasan Ali so ninu iwe iroyin " imole islam" pe: okan ninu awon ore oun ti o je elesin Barhama sope: '' mo ri pe ojise esin Islam ni eni pataki ti o pe julo ninu gbogbo awon omoniyan'' amoye Hasan beere wipe '' ki lo ri?'' o si dahun wipe '' mo se akiyesi lara re awon iwa abiyi orisirisi ati awon isesi ti ko legbe ati awon iroyin eleyin ti ko si lara enikankan ninu itan omoniyan: o je oba ti gbogbo ilu ju arawon sile fun pe ki o ma se bi o ba se wu, sugbon pelu bee, o je oluteriba onirele. O gba wipe oun ko ni nkankan atipe Olohun nikan ni olukapa. Awon rakunmi a ma gbe awon orisirisi apepe-oro ati dukia wa si odo re, pelu bee o gbe igbesi aye alaini ti won ko ni da ina ni ile re fun aimoye ojo! Aimoye igba lo ma nsun lebi! Bakan naa o je akogun agba ti o ma ndari omo-ogun to kere lonka ati nkan ija lati koju egbeegberun omo-ogun ti o kun fun awon oun ija orisirisi, ti yoo si bori won.
      O feran ibagbepo alafia, ipari ija ati ifowosi iwe adehun alafia ni asiko ti o jepe egbeegberun akikanju ati onigboya ninu awon omo-ogun lo wa leyin re. O je akin onigboya ti o ma nkoju egbeegberun awon ota ni oun nikan. O je olokan riro, alaanu ati onike. O korira tita eje omoniyan sile. O ma ronu pupo lori orikusu ile larubawa lapapo, ti eleyi ko si di ojuse lowo lodo awon ara ile re, iyawo ni tabi awon omo. O ni akolekan alamori awon talaka ati alaini. O mojuto oro awon ti won gbagbe adeda won ti won si sina kuro loju ona, bawo ni won yoo se pada si oju ona. Lakotan o je eda kan ti o ni akolekan oro gbogbo aye. O je olujosin fun olohun ni ododo. Ko wa aye moya. O gbe ninu aye leni ti ko kaye kun nkankan, toripe okan ko sopo mo nkankan ju olohun lo ati sise oun ti yoo yo olohun ninu.
      Kii gbesan lara eniyan nitori ara re, o ma nse adua daada fun awon ota re, o si ma ngbero daada rowon. Sugbon kii se amojukoro fun awon ota Olohun kii si fi won sile. O ma nkilo fun awon ti won gunri kuro loju ona Olohun. O si ma nse adehun iya ina Jahanama fun won. O je eni to ri aye sa, olujosin temi tara, o ma nkirun loru fun iranti olohun ati lati maa pe. Gege bi o se je akinkanju akoni okunrin ogun, bee na lo je Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) onilakaye ti o gbon berebere, Anabi Olohun ti o jina si ijegaba ati abosi koda lasiko ti o bori awon ilu ati awon iran.
      Eni ti a se lati ibi ewe igi dabidun ni ibusun re, irori ti won se latara koriko lo ma n rogboku le lori, ni asiko ti ko ye ki a pe ni nkankan ju asiwaju awon larubawa tabi oba awon larubawa lo. Awon ara ile re ma nwa ninu osi ati aini ti o lagbara leyin ti awon oro repete ba wole to wa lati gbogbo origun orikusu ile larubawa. Yoo wa ni gbagede mosalasi re pelu opolopo nkan, ti omo re pataki, Fatima, yoo si wa sodo re leni ti o ke irora latara inira ti o nri nibi gbigbe awo omi ti o wuwo ati fifi owo lo nkan eyi ti o ti da apa si lowo, ti awo omi si ti da apa si lara. Ni asiko yi ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) npin awon oro ogun (eru lokunrin ati lobinrin) lowo laarin awon musulumi. Ko fun omo re ni nkankan ninu oro ogun naa ayafi adua ti o ko pe ki o lo ma fi be olohun! Ore re Umar omo Khatab (Olohun ko yonu si) wole sinu yara re ni ojo kan, ko ri nibe ju eni ewe igi dabidun ti ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) fi nsun, ti o si ti fa ila si ara re, bakan naa ounje ti o wa nile re ko ju owo kan okababa lo, ati rakunmi re ti won so mo opo. Eleyi ni gbogbo oun ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ni lasiko ti oun ti o to idaji ile larubawa wa ni abe ikapani re! nigba ti Umar ri eleyi omije bere si ni da ni oju re, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) bi leere wipe:
"ما يبكيك يا عمر؟ فقال: وما لي لا أبكي إن قيصر وكسرى يتمتعان بالدنيا وينعمان بنعيمها وإن رسول الله لا يملك إلا ما أرى، فقال له الرسول :" أما ترضى يا عمر أن يكون ذلك نصيب كسرى وقيصر من نعيم الدنيا وتكون لنا الآخرة خالصة من دون الناس ؟!"
     '' ki lo npa e lekun ire Umar? O dahun wipe '' bawo ni mi o se ni sunkun, nigba ti oba Qaysar ati Kisra nje igbadun aye ati idera re, ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ko si ni ju awon oun ti mo ri wonyi lo'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) so fun pe '' se ko wa te o lorun, ire Umar, ki awon nkan wonyi je ipin Kisra ati Qaysar ninu idera aye, ki idera torun si je tawa nikan?
      Nigba ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) fe gba ilu Makkah. O sele mo awon ara ilu pelu awon omo ogun re. abu Sufyan wa pelu Al Abas ti se egbon baba Ojise Olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ti awon mejeeji si n wo awon omo ogun musulumi ti awon eekan ninu awon akoni si siwaju won. Abu Sufyan ni asiko yi si wa lori titako esin Islam, sugbon eru ba nigba ti o ri pupo onka awon omo ogun musulumi ati awon iran ti o ti dara po mo won, ati bi won se n wo lo ni abala ile ti o teju ni ilu Makkah gege bi agbara ojo nla ti ko si oun ti o le da lona. O so fun enikeji re wipe '' ire Abas, dajudaju omo aburo re ti di oba nla! Abas si da lohun pe (toripe oun ko ronu lo si ona ti ore re ronu lo) eleyi kii se ti oloba rara, ire Abu Sufyan, sugbon ije Anabi Olohun ati ojise re'' (Al Bukhari)
      Adiy ti iran Tayihi, omo Hatim, ti o je gbajumo olutore ti won ma nfi se apejuwe nibi ore tita ati aanu. O je asiwaju iran Tayihi. O wa si ijoko Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ni ojo kan, o si wa ninu esin kirisiteni ni asiko yi. O se akiyesi gbigbe ola ati iyi fun ni ti awon omoleyin Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) nse fun, ni asiko ti won nwo awon nkan ogun won. Oro ko ye Adiy mo, ti o si nbi ara re leere wipe '' se oba awon oba niyi ni tabi ojise Olohun? Laarin igba ti o nro eleyi lowo ni arabinrin alaini kan ninu awon eru ilu Madina wa si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba), o si sope: '' mo fe so oro asiri fun o ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba)'' o si da lohun wipe:
 "انظري في أي سكك (جمع سكة وهي الطريق) المدينة شئت أخلو لك، ثم نهض معها وقضى لها حاجتها"
     '' wo eyikeyi aye ti o ba wu o ninu ilu Madina yi lati so oro naa, ma tele o'' o tele obinrin naa o si ba yanju oun to nfe". (Abu Dawud).
      Nigba ti Adiy ri iwa irera eni sile yi lara Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) pelu pe o wa laarin awon omoleyin re gegebi obo laarin awon emewa re. ododo foju han si Adiy, o si ni amodaju pe dajudaju okan ninu awon ojise olohun (ike ati ola olohun ko mo ba gbogbo won) ni eleyi. Bayi ni o yo agbelebu re sonu ti o si darapo mo awon musulumi (Imole Islam).
      A o so die ninu awon oro ti awon olukeko esin Islam sugbon ti won ki se musulumi so nipa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba). Bi o tile jepe awa gege bi elesin Islam a ko ni bukata si awon oro wonyi sugbon a fe so awon oro naa nitori awon idi meji pataki.
     Alakoko; ki awon musulumi ti won nfi oruko lasan se esin le ka, ki won si mo oun ti awon ti kii se elesin Islam so nipa anabi ati ojise won, boya o le je okunfa ki won pada niti ododo si ibi titele Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba).
     Elekeji: ki awon ti ki se elesin Islam le ka, ki won si le mo pataki Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) alafokantan, lati enu awon eniyan won ti won jo je elede kan naa. Boya won le mona latara re, ki o si tun le je ibere iwadi fun won lati mo nipa esin Islam. O se pataki fun iru awon eniyan wonyi lati lo lakaye won, laifi ti eleyameya se, lati le da ododo mo yato si iro ati lati mo oju ona ola yato si igbe. A be Olohun ki o si igbaya awon eniyan wonyi fun ododo kio si fi won mona losi oju ona ola.

Abd Ar-Rahman omo Abd Al-Kareem Ash-Sheha
 
www.islamland.com


Tani Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) Muhammad?
Iran re:
      Oun ni baba Al Qasim, ti oruko re nje Muhammad omo Abdullah omo Abdul Mutalib. Iran re pari si odo Adnan ninu awon omo anabi Ismaeel omo anabi Ibrahim ti se ore aayo Olohun (ike ati ola Olohun ko mo ba gbogbo won). Iya re ni Aminah omo Wahab, iran re pari bakan naa si odo Adnan ninu awon omo anabi Ismaeel omo anabi Ibrahim ti se ore aayo Olohun. (ike ati ola Olohun ko mo ba gbogbo won).
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) sope: '' dajudaju olohun sa Kinanah lesa ninu awon omo Anabi Ismaeel, o si sa Quraysh lesa ninu iran kinanah, o si sa ebi Hashim lesa ninu awon Quraysh, o si sa mi lesa ninu ebi Hashim. (Muslim)
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) je eni ti o lola julo ni iran laarin awon eda, ni ibamu si ipele iran re. koda awon ota naa jeri si pe oun ni eni ti o lola ju ni iran. Abu Sufyan ti o je olori awon ota Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) siwaju ki o to di musulumi, jeri si nini ola iran re lodo Hirqil ti se oba ilu Romu. Abdullah omo Abas sope: '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) kowe ranse si Qaysar lati pe si inu esin Islam. O fi iwe naa ran Dihyatu l kalbi, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) pa lase ki o fi iwe naa jise fun oba Basra lati fi jise fun oba Qaysar. Nigba ti olohun fun Qasray ni isegun lori omo ogun Farisi, o gbera lati ilu Himsi lo si ilu Iliyai (Jerusalemu) lati dupe fun olohun lori oore ti o se fun. Nigba ti iwe ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) de sodo Qaysar ti o si ka, o sope: '' e bami wa awon eniyan re, kin le bi leere nipa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba).
      Omo Abas sope: '' Abu Sufyan so fun mi pe oun wa ni ilu Shamu pelu awon onisowo ninu iran Quraysh ti won wa fun tita ati rira ni asiko atunse laarin awon ati Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba). Abu Sufyan sope '' iranse oba Qaysar ba wa ni ilu Shamu, emi ati awon eniyan mi si tele titi ti a fi wo ilu Iliyai. A ba Qaysar ti o joko si aafin re pelu ade re lori, awon atokun ilu Romu si wa ni ayika re. o so fun ongbifo re pe '' bi won leere wipe ewo ninu won lo je molebi arakunrin ti o n pe ara re ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba)?'' Abu Sufyan ni mo dahun wipe '' emi ni mo sun mo ju ni iran'' o si beere wipe '' kinni asopo ti o wa laarin eyin mejeeji? Mo si dahun wipe '' omo egbon baba mi ni''. Ni ojo yi ko si elomiran pelu wa ni irin ajo ninu iran Abdu Manafi ayafi emi nikan. O si dahun wipe '' sun si bi'' o si pa awon eniyan mi lase ki gbogbo won bo si eyin mi. O si dahun wipe '' mo fee beere nipa arakunrin yi lowo re, o ko gbodo paro fun mi'' Abu Sufyan sope '' ti kii ba se tori ojuti, ki won mo sope mo npuro, mi o ba paro mo''. Leyin eleyi lo wa beere awon ibeere wonyi:
      Bawo ni ebi re se je laarin yin? Abu Sufyan dahun wipe '' omo nibi niran niise.
      Nje enikankan ninu iran yin pe ara re ni ojise siwaju re? Abu sufyan dahun wipe ''rara''
      Nje enikankan ninu awon baba re joba ri? Abu Sufyan dahun pe ''rara.''
      Nje awon abiyi eniyan ni won ntele tabi awon alaini ati awon eni yepere? Abu Sufyan dahu wipe '' awon alaini ati awon eni yepere''
      Nje won nlekun ni onka ni tabi won ndinku? Abu Sufyan dahun wipe '' won nlekun si ni''
      Nje enikan sope oun o se esin naa mo ninu won bi? Abu Sufyan dahun wipe '' rara''
      Nje emo si opuro laari yin siwaju ki o to pe ara re ni ojise olohun? Abu Sufyan dahun pe ''rara''
      Nje emo si onijanba laarin yin? Abu Sufyan dahun wipe ''rara''
      Nje ejagun pelu re bi? Abu Sufyan dahun wipe '' beeni''
      Bawo ni awon ogun naa se ri? Abu Sufyan dahun wipe '' igbakan a o segun re, igba miran yoo segun wa''
      Kin ni awon oun ti o npayin lase re? Abu Sufyan si dahun pe ''e maa josin fun olohun kan soso, e ko gbodo se ebo pelu re,e gbe oun ti awon baba yin nso ju sile. O si tun ma npawa lase irun kiki, ododo siso, ilamojukuro (itelorun) ati imaa da okun ibi po''.
      Leyin naa ni oba naa dahun wipe '' mo bi o lere nipa iran re, o ni omo nibi niran ni, gege bee ni awon ojise olohun, inu iran abiyi laarin awon eniyan won ni won ti mo njade. Mo bi o leere, nje enikankan ninu yin so iru oro yi siwaju re? o si dahun wipe rara, ti o ba je pe enikan so siwaju re ni, mi o ba sope o nkose eni to siwaju re ni. Mo bi o leere wipe nje enikan ninu iran yin joba ri? O si dahun wipe rara. Ka ni beeni, mi o ba sope o fe gba ipo awon baba re ni. Mo bi o leere wipe nje e mo si opuro bi? O si dahun pe rara. Mo wa mo pe ko rorun fun anikan lati ma paro fun omoniyan ko wa mo paro nipa Olohun. Mo bi o leere nipa awon to ntele, o si dahun wipe awon alaini ati awon eniyan yepere. Awon wonyi naa lo ma ntele awon Anabi Olohun. Mo bi o leere se won ndinku ni tabi won nlekun? O si dahun wipe won nlekun ni. Bayi nii oro igbagbo se ma nri titi ti yoo fi pe. Mo bi o leere wipe nje enikankan ninu won sope oun o se mo leyin igbagbo, o si dahun pe rara. Bi oro igbagbo se ri niyi nigba ti o ba wonu emi. Mo bi o leere nje oni ijanba ni bi? O si dahun wipe rara. Beeni awon Ojise Olohun won kii se ijanba. Mo tun bi o leere ki ni oun ti o npe yin si? O si dahun wipe mimo josin fun Olohun kan soso, gbigbe ebo sise ju sile, gbigbe oun ti awon baba yin nso ju sile. O ma npayin lase irun kiki, ododo siso, ilamojukuro (itelorun) ati mimo da okun ibi po''.
      Hiriqilu wa so bayi pe '' to ba jepe ododo ni oun ti o so wonyi, arakunrin naa yoo jogun ilu mi yi. Mo mo wipe won yoo gbe dide sugbon mi o mo pe aarin yin ni yoo je. Ka ni mo wa lodo re ni, mi o ba fi ara mi sile fun. Leyin naa lo gba iwe ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko maa ba) fi ranse si, o si ka bayi ''
بِسْمِ اللَّهِ الرحمن الرَّحِيمِ من مُحَمَّدٍ عبد اللَّهِ وَرَسُولِهِ إلى هِرَقْلَ عَظِيمِ الرُّومِ سَلَامٌ على من اتَّبَعَ الْهُدَى أَمَّا بَعْدُ فَإِنِّي أَدْعُوكَ بِدِعَايَةِ الْإِسْلَامِ أَسْلِمْ تَسْلَمْ يُؤْتِكَ الله أَجْرَكَ مَرَّتَيْنِ فَإِنْ تَوَلَّيْتَ فإن عَلَيْكَ إِثْمَ الْأَرِيسِيِّينَ "قل يا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إلى كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ ألا نَعْبُدَ إلا اللَّهَ ولا نُشْرِكَ بِهِ شيئا ولا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا من دُونِ اللَّهِ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ "
ni oruko Olohun, Oba ajoke aye, Oba asake orun, lati odo Muhammad eru ati Ojise Olohun si olola Roomu Hirikilu. Alafia Olohun ki o ma ba eni to ba tele oju ona ola, mo npe o si esin Islam, ju ara re sile fun Olohun ki o le ba la ninu iya, Olohun yoo si san o lesan ni ilopo meji. Sugbon ti o ba ko, ese gbogbo arisiyiin (awon ara ilu re) yoo wa lorun re, '' sope eyin ti a fun ni tira, e wa sibi gbolohun to se deede laarin awa ati eyin, (eyi tii se) a ko gbodo josin fun elomiran leyin olohun, a ko gbodo se ebo pelu re, apakan wa ko gbodo mu apakeji ni oluwa leyin Olohun. Ti won ba ko lati se bee, e sofun won pe '' e je eleri wa pe musulumi ni wa''.
 Nigba ti o ka iwe naa tan awon emewa, oloye ati otokulu ti won wa pelu re pariwo ti ohun won si lo soke, sugbon mi o mo oun ti won so. Leyin naa o ni ki a jade. Nigba ti a de ita mo so fun awon eniyan mi wipe '' oro omo Abu Kabsha ti wa lagbara bayi. Oba ilu Romu lo ma nberu yi''. Mo fi Olohun bura, mo nbe leni iyepere tio mo amodaju wipe esin Islam yoo bori, titi ti olohun fi wa sipaya okan mi fun Islam ni asiko ti mo korira re''. (Al Bukhari).


BI WON SE BI ATI DIDAGBA SOKE RE
Won bi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ni odun ogorun marun ati mokanle laadorin (571AD) si inu iran Qurayshi, eyi ti o je eekan ti gbogbo awon iran larubawa si ma nse aponle ati iyi fun ni ilu Makkah, eyi ti o je olu ilu esin fun gbogbo orikusu ile larubawa. Owa ni Inu ilu yi ile alaponle (Kabah) ti anabi Ibrahim ti o je baba awon Anabi Olohun (ike ati ola Olohun ko mo ba gbogbo won) ati omo re Ismaeel jo ko. Awon larubawa ma nse irin ajo esin (hajji) lo si ibe, ti won si ma nyipo ile naa. Baba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ku nigba ti o wa ninu oyun, ti iya re na si papo da leyin igba die ti o bi. O gbe igbesi aye omo orukan ti baba baba re Abdul Mutalib si gba to. Nigba ti baba baba re papo da, o bo sodo egbon baba re Abu Talib.
 Iran re ati awon iran ti o rokirika won ma nse ijosin fun awon orisa ti won mo latara igi, okuta ati golu. Won gbe awon orisa wonyi yika Kabah. Won si ni igbagbo wipe awon orisa yi lagbara lati fi daadaa kan ni tabi mu aburu kuro fun ni. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) lo gbogbo igbesi aye re pelu ododo ati pelu ifokantan. Won ko mo si oluye adehun tabi opuro eniyan, bakan naa ki se onijamba tabi eletan eniyan. Awon eniyan re mo si eni ti o se fokantan. Won si ma nfi awon dukia won pamo si lodo nigba ti won ba fe lo si irin ajo. Won mo si olododo latara wipe isesi ati oro ododo lo ma n jade lati odo re. O je oniwa rere, oloro tutu, eni to da lawon ti o si mo oro so, o feran daadaa fun awon eniyan. Awon eniyan re feran re pupo, won si ma n pataki re, at'onile at'alejo lo ma nse aponle re. o rewa leniyan, awo mole lo si ni pelu (ike ati ola olohun ko moo ba). O rewa leda ati niwa, iroyin re koja siso. Olohun sope:
{ وَإِنَّكَ لَعَلَى خُلُقٍ عَظِيمٍ}
     '' atipe dajudaju ire je eniti o ni iwa ti o dara julo'' Q68:4.
      Th. Carlyle so nipa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ninu iwe re '' Awon Akoni '' wipe '' o foju han wipe Muhammad lati kekere re je odo ti o ni lakaye, ti o si ni arojinle. Awon eniyan re ma n pe ni '' eni to se gbekele'' (eni to lododo ti o si ma n pe adehun). Olododo ni ninu oro, ironu ati isesi. Bakan naa oro kan ko ni jade lenu re ayafi ki o kun fun ogbon ati oye. O ma n ba dake pupo, ki soro ayafi ni aye ti oro yo ti se anfani. Ti o ba si soro oro re yoo kun fun lakaye ati ogbon. A ri lara re pe o je eni ti o fese mule nibi ipile re, o si je onipinnu to daju. O je eni ti o jina si awon oro ti ko wulo.
      O je olutore, ati oluse daadaa ti si ma nse pele pelu awon eniyan, o je olupaya olohun, onipo, omoluwabi, olododo igbiyanju. Bakan naa o je eni ti o ko awon eniyan mara, ki jiyan ti ko ni anfani, oloju tutu aberin muse, ibagbepo re rorun pupo, adun barin eniyan lo je, o ma n se awada o si ma n sere. Ju gbogbo e lo, o je eni ti oju re ma n tan imole pelu erin muse ti o wa lati inu okan ododo. O je eni to ma n tete ronu lori alamori ti lakaye re ki sun. Adamo re lagbara pupo. Ko lo si ile iwe rara bakan naa oluko kan ko ko leko ri! O ga ni ipo pupo. O pe ojuse re ni ile aye loun nikan ni ona ti o dara ti o si pe julo''
      Siwaju ki o to di Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba), o feran lati ma dawa ni oun nikan. O si ma n lo se ijosin fun oru awon ojo pupo ninu koto Hira. O jina tefetefe si awon oun ti awon eniyan re n se ninu awon isesi aimokan. Ko ba won mu oti ri bakan naa ko foribale, josin, se adehun tabi pa nkan si idi orisa ri gege bi awon eniyan re se ma n se. o se ise adaranje fun awon eniyan re. o so bayi pe:
 " ما بعث الله نبياً إلا رعى الغنم " فقال أصحابه: وأنت؟ فقال:"نعم، كنت أرعاها على قراريط لأهل مكة " (صحيح البخاري).
     '' Olohun ko ni gbe Anabi kan dide ayafi ki o da eran je'' awon omoleyin beere wipe '' ati ire naa?'' o si dahun wipe '' beeni, mo je eni ti ma n da eran je fun awon ara Makkah, lori iye owo kan'' (Al Bukhari).
 Nigba ti o di omo ogoji odun, imisi sokale fun lati oke samon, nigba ti o wa ni ilu Makkah, ninu koto Hira ti o ti ma lo se ijosin. Aisha, iya gbogbo onigbagbo ododo, ti se iyawo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) (Olohun ko yonu si) sope:
" أول ما بدئ به رسول الله ﷺ من الوحي الرؤيا الصالحة في النوم، فكان لا يرى رؤيا إلا جاءت مثل فلق الصبح ثم حبب إليه الخلاء، وكان يخلو بغار حراء فيتحنث فيه, وهو التعبد الليالي ذوات العدد قبل أن ينزع إلى أهله ويتزود لذلك ثم يرجع إلى خديجة فيتزود لمثلها, حتى جاءه الحق وهو في غار حراء, فجاءه الملك فقال: اقرأ قال:"ما أنا بقارئ. قال: فأخذني فغطني حتى بلغ مني الجهد ثم أرسلني فقال: اقرأ. قلت: ما أنا بقارئ. فأخذني فغطني الثانية حتى بلغ مني الجهد ثم أرسلني فقال: اقرأ فقلت: ما أنا بقارئ فأخذني فغطني الثالثة ثم أرسلني فقال: }اقْرَأْ بِاسْمِ رَبِّكَ الَّذِي خَلَقَ (1) خَلَقَ الْإِنْسَانَ مِنْ عَلَقٍ (2) اقْرَأْ وَرَبُّكَ الْأَكْرَمُ (3) الَّذِي عَلَّمَ بِالْقَلَمِ (4) عَلَّمَ الْإِنْسَانَ مَا لَمْ يَعْلَمْ (5){ فرجع بها رسول الله ﷺ يرجف فؤاده فدخل على خديجة بنت خويلد رضي الله عنها فقال:" زملوني زملوني " فزملوه حتى ذهب عنه الروع فقال لخديجة وأخبرها الخبر:" لقد خشيت على نفسي ". فقالت خديجة: كلا والله ما يخزيك الله أبدا, إنك لتصل الرحم, وتحمل الكل وتكسب المعدوم, وتقري الضيف, وتعين على نوائب الحق, فانطلقت به خديجة حتى أتت به ورقة بن نوفل بن أسد بن عبد العزى بن عم خديجة, وكان امرأً تنصر في الجاهلية, وكان يكتب الكتاب العبراني فيكتب من الإنجيل بالعبرانية ما شاء الله أن يكتب, وكان شيخا كبيرا قد عمي, فقالت له خديجة: يا بن عم اسمع من ابن أخيك. فقال له ورقة:يا بن أخي ماذا ترى؟ فأخبره رسول الله صلى الله عليه و السلم خبر ما رأى فقال له ورقة: هذا الناموس الذي أنزل الله على موسى يا ليتني فيها جذعاً ليتني أكون حيا إذ يخرجك قومك, فقال رسول الله: "أو مخرجي هم؟". قال: نعم لم يأت رجل قط بمثل ما جئت به إلا عودي, وإن يدركني يومك أنصرك نصرا مؤزرا, ثم لم ينشب ورقة أن توفي وفَتَر الوحي" (صحيح البخاري ومسلم).
     '' akoko oun ti o bere fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ninu imisi ni ala ododo ti o ma n la loju orun, ko ni la ala kan ayafi ko sele ni deede bi o se la. Leyin naa lo bere si ni feran lati ma dawa. O si ma nlo si inu koto Hira ti si ma nse ijosin nibe fun awon ojo to po die siwaju ki o to pada lati lo pese awon oun jije ati mimu fun deede asiko miran. Ti o ba ti setan yoo pada sodo Khadijah lati pese fun iru asiko miran. Titi ti ododo fi wa de ba ni asiko ti n be ninu koto yi. Malaika naa wa ba, o si so fun pe '' mo ka'' o si dahu wipe '' mi o mo nkan ka'' o sope '' o mumi o si fun mi mora gidigidi'' leyin naa o ju mi sile o si tun sope '' mo ka'' mo si dahun wipe '' mi o mo nkan ka'' o tun fun mi mora gidigidi leekeji, leyin naa o fi mi sile o si tun sope '' mo ka'' mo si dahun wipe '' mi o mo nkan ka'' o si tun fun mi mora gidigidi ni eleeketa, leyin naa o fi mi sile o si sope '' mo ka ni oruko olohun re ti o da eda، o da omoniyan lati ibi eje kiki, mo ka, olohun re ni alaponle، eyi to ko ni leko pelu gege, o fi mo omoniyan oun ti ko mo tele'' Q96:1 5. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) pada sile leni aya re nja kikankikan. O wole lo ba Khadijah omo Khuwaylad (Olohun ko yonu si) o si so pe ''e daso bomi, e daso bomi'' won si daso bo ti iberu to wa lara re si fi kuro. O so fun Khadijah oun ti o ri o si sope '' eru ara mi nba mi '' Khadijah si dahun wipe '' oro ko ri bi o se ro, Olohun ko ni doju ti o lailai. Iwo ti o ma da ibi po, ti o si ma n la bukata awon eniyan borun, ti o si ma ntore owo fun eni ti ko ni, ti o ma n pese jije ati mimu fun alejo, ti o si ma n ran awon eniyan lowo lori oun ti o ba de ba won lori ododo.
      Khadijah (Olohun ko yonu si) tete mu lo si odo Waraqatu omo Naofal omo Asad omo Abdul Uza omo egbon baba Khadijah. Baba yi je elesin kirisiteni lati igba aimokan. O je enikan ti o ma nko iwe ni ede Hibru, o si ma nko tira Injila pelu ede Hibru bi olohun se fun ni iyonda mo. Baba yi ti di arugbo ti oju re si ti fo. Khadijah (Olohun ko yonu si) so bayi pe '' ire omo egbon baba mi, teti gbo oun ti omo aburo re fe so'' Waraqatu si dahun wipe '' ire omo aburo mi, ki lo sele?'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) si salaye oun ti o ri fun. Waraqatu si dahun wipe '' iranse lati odo olohun ni, oun ni olohun ran si Anabi Musa (ike ati ola Olohun ki o ma ba).
      Bawo ni o ba se ri kin je odo? Bawo ni o ba se ri kin wa laye, nigba ti awon eniyan re ba le o jade (ni ilu)?''. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) beere wipe '' se won o le mi jade ni?'' o si dahun wipe '' beeni, enikan ko mu iru oun ti o muwa yi ayafi ki won mu lota, ti mo ba n be laye ni igba naa, ma ran o lowo ni iranlowo ti o ni itumo '' sugbon ko pe si igbayi ti Waraqatu fi jade laye. Imisi si duro die ki o tun to ma sokale fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba)''.( Al Bukhari ati Muslim).
      Ogba oro yi (Q96) ni o je ibere ije Anabi Olohun (ike ati ola Olohun ko mo ba) re, leyin naa ni oro Olohun miran tun sokale bayi pe:
 }يَا أَيُّهَا الْمُدَّثِّرُ (1) قُمْ فَأَنْذِرْ (2) وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ (3) وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ (4) وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ (5){
     '' ire ti o da aso bori mole، dide ki o ma se kilokilo ،ki o si ma se agbega fun Olohun re \\ ki o si ma se aso re ni mimo \\ ki o si jina si orisa\\ Q74:1-5.
     Eleyi si je ibere jije Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ati ipepe re. o bere ipepe itagbangba pelu pipe awon eniyan re ninu awon ara Makkah. Sugbon atako ati ifunlemoni ni o ba pade lati odo won. Idi nipe ipepe ti o mu wa yi je ajoji si won. Ipepe kan ti o ko gbogbo eto igbesi aye won sinu patapata; ilana ijosin, iselu ati isejoba, eto inawo ati eto awujo. Ipepe yi ko duro lori pipe won sibi mima josin fun olohun nikan soso, tabi ki won kuro nibi ijosin fun elomiran, tabi fifi rinle aimokan won ati awon orisa ti won n josin fun leyin olohun, biko sepe o se awon ilana igbadun, orin ati imo se igberaga won ni eewo. O se owo ele, agbere, tete tita ati oti ni eewo. O pe won lo sibi deede sise laarin gbogbo eniyan, atipe ko si ajulo fun enikan lori enikeji ayafi latara iberu olohun.
      Bawo ni iran Qurayshi se fe yonu si ki awon ati eru jo wa ni ipo kan naa? Nigba ti o je pe awon ni asiwaju iran larubawa. Oro ko duro sibi titako ati ifi esun awon oun ti ko sele kan Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba), gegebi ki won pe ni opuro, were ati opidan, awon iroyin ti won ko le pe siwaju ki o to bere ipepe re. won lo awon iroyin buruku yi lati fi tan awon alaimokan je. koda won tun fi inira ti ara kan bakan naa. Abdullah omo Masu'd sope:
"بينما رسول الله ﷺ قائم يصلي عند الكعبة وجمع قريش في مجالسهم إذ قال قائل منهم: ألا تنظرون إلى هذا المرائي! أيكم يقوم إلى جزور آل فلان فيعمد إلى فرثها ودمها وسلاها فيجيء به ثم يمهله, حتى إذا سجد وضعه بين كتفيه؟ فانبعث أشقاهم, فلما سجد رسول الله ﷺ وضعه بين كتفيه, وثبت النبي ﷺ ساجدا, فضحكوا حتى مال بعضهم إلى بعض من الضحك, فانطلق منطلق إلى فاطمة عليها السلام وهي جويرية فأقبلت تسعى, وثبت النبي ﷺ ساجدا حتى ألقته عنه وأقبلت عليهم تسبهم". (صحيح البخاري)
     '' nigba ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) n kirun ni Kabah ti awon iran Qurayshi si kora jo si aye ijoko won, enikan ninu won dahun wipe '' e wa ri okunrin onise karimi yi bi? Tani ninu yin, ni yoo lo si agbo rakunmi idile lagbaja ti yoo si gbe ole-inu (rakunmi), ati eje re pelu apo ile omo wa, ti yoo si yo kelekele wo masalasi, ti yoo si gbe si lorun nigba ti o ba forikanle? Olori buruku inu won ba dide. Nigba ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) forikanle o si gbe si lorun! Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) wa ni iforikanle bee, won si fi n se yeye titi ti won si n subu lu ara won. Enikan sare lo so fun Fatimah (Olohun ko yonu si), o je omokekere ni asiko yi, o de loju ese, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) si wa lori iforikanle, o gbe ifun eran naa kuro lori Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba), osi bere si ni bu awon eniyan yi. (Al Bukhari)
      Munibu Al azdi sope:
رأيت الرسول ﷺ في الجاهلية وهو يقول:" يا أيها الناس قولوا لاإله إلا الله تفلحوا " فمنهم من تفل في وجهه، ومنهم من حثا عليه التراب، ومنهم من سبه، حتى انتصف النهار، فأقبلت جارية بعس - قدح كبير -من ماء فغسل وجهه ويده فقال:" يا بنية لا تخشي على أبيك عيلة (وفي رواية غلبة) ولاذلة " (المعجم الكبير للطبراني).
     '' mori Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) nigba aimokan ti ma n sope '' eyin eniyan, e sope ko si eni ti o leto si ijosin leyin olohun, ki e le ba jere''. O nbe ninu awon eniyan yi eni ti yoo tuto si lara, o nbe ninu won eni ti yoo da yerupe si lara, o si nbe ninu won eni ti yoo ma bu, titi ti o fi di idameji osan, omobinrin ti o gbe igba omi nla lowo si jade si, o fo oju ati owo re, o si sope '' ire omobinrin mi kekere, mo se paya osi (tabi ijakule) ati iyepere lori baba re (Al mujamu l kabeer).
     Urwah omo Zubayr sope mo bi Abdullah omo A'mru omo Aa's (Olohun ko yonu si won) nipa oun ti o buru ju ti awon osebo se fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba),
قال: "أقبل عقبة بن أبي معيط ورسول الله ﷺ يصلي عند الكعبة, فلوى ثوبه في عنقه فخنقه خنقاً شديداً، فأقبل أبو بكر رضي الله عنه فأخذ بمنكبه فدفعه عن رسول الله ﷺ فقال: أتقتلون رجلاً أن يقول ربي الله وقد جاءكم بالبينات من ربكم ؟ (صحيح البخاري).
    O so bayi pe '' U'qbah omo Abu MuaI't yo jade ni asiko ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) n kirun lowo ni Kabah, o si we aso re mo lorun, o si fun tagbara tagbara, Abu Bakri (Olohun ko yonu si) jade wa, o fa ejika re, o si ti kuro lara Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba), o si so bayi pe '' se e fe pa ni, nitori pe o nso pe Olohun ti oun ni Allah, leyin igba ti o si ti mu awon eri wa fun yin?'' (Al Bukhari).
      Awon isele wonyi ko di Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) lowo lati tesiwaju nibi ise ipepe re. o ma nlo pe awon idile idile, ti won ba wa si ilu Makkah fun ise Hajj, sinu esin Islam. Awon eniyan ti onka won kere lati ilu Yathrib (Madina) ni won gbaagbo, won se adehun iranlowo ati idaabobo fun un ti o ba wa si ilu won. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ran Musa'b omo U'mayr, okan ninu awon omoleyin re, lati lo ma ko won ni eko esin islam. Leyin ifunlemo ati atako ti oun ati awon ti o gbaagbo ninu awon ole ilu Makkah, ba pade lodo awon eniyan won. Olohun yonda fun won lati se irin ajo esin lo si ilu Madina Onimole. Awon ara ilu Madina gbawon towo tese. Eleyi si ni ibere titanka ipepe esin Islam. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) fi ilu Madina se ile, o si bere si ni ka Al Quran fun won, bakan naa lo si nko won ni awon idajo esin.
      Iwa eleyin ati iroyin ti ko legbe ti n be fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ni oripa lara awon ara ilu Madina, debi wipe won feran re ju ara won lo! Won si ma nse idije laarin ara won nibi gbigbo bukata re, ti won si tun ma nna ile ati ona won lati te lorun. Awujo won di awujo igbagbo ati isetolohun, ti orire wa yiwon po ni gbogbo origun. Ife, ajosepo ati ijomo-iya ododo ni oun ti o gbajumo laarin won. Awon olowo ati awon alaini, gbajumo ati eniyepere, eniyan funfun ati eniyan dudu, larubawa ati eni ti ki se larubawa di nkan kan naa laarin ara awon latara esin Islam alaponle yi. Ko si ajulo tabi onpinya laarin won ayafi labala iberu Olohun. Leyin odun kan ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ti kale si ilu Madina, igbenan woju ara eni bere laarin awon ati awon osebo ilu Makkah.
      Ogun yi sele latara pe won ko yonu si idagbasoke ti n ba ipepe esin Islam. Ogun akoko ti o sele ninu itan Islam ni won n pe ni Ogun Badr. Ogun yi sele laarin awon iko meji ti won ko se deedee ara won rara, yala labala onka omo ogun ni tabi awon oun ija. Onka omo ogun musulumi ni ojo yi je ogorun meta ati merinla (314) nigba ti onka omo ogun awon osebo si je egberun mewa (10,000). Olohun ti ola re ga ran ojise re ati awon musulumi lowo, won si bori ogun naa! Opolopo ogun miran lo waye laarin awon musulumi ati awon osebo. Sugbon leyin odun kejo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) ko awon omo ogun ti onka won to egberun mewa (10,000) jo lati doju ko ilu Makkah. O wo ilu Makkah leni ti o gba ilu naa, ti o si bori awon iran ati awon eniyan re ti won fi inira oniranran kan an, ti won si fi iya orisirisi je awon omoleyin re titi ti won fi fi dukia owo omo ati ilu won sile. Sugbon won pada bori ni ibori ti o ni apere. Won si ma n pe odun naa ni ODUN IGBAJOBA (ilu Makkah). Olohun ti ola re ga so nipa isele yi bayi pe:
[إِذَا جَاءَ نَصْرُ اللَّهِ وَالْفَتْحُ (1) وَرَأَيْتَ النَّاسَ يَدْخُلُونَ فِي دِينِ اللَّهِ أَفْوَاجًا (2) فَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ وَاسْتَغْفِرْهُ إِنَّهُ كَانَ تَوَّابًا (3)]
     '' nigba ti aranse olohun ba de ati isegun \\ atipe ire yoo ri awon eniyan ti won yoo ma wo inu esin ti olohun nijo nijo \\ nitorina ma se afomo pelu ope didu fun olohun re, ki o si ma toro idariji lowo Re. dajudaju Oun je Olugba ironu piwada\\ Q110: 1-3.
     Eleyi ni o si se okunfa ki opolopo won di elesin Islam. Leyin naa ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) pada si ilu Madina. Leyin asiko die o gbero lati lo se Hajj ni ilu Makkah pelu egberun lona ogorun ati egberun merinla (114,000) omoleyin. Hajj yi ni won ma n pe ni Hajj idegbere (Hajjatu l wada'). Toripe oun ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) fi dagbere fun awon musulumi atipe asiko iku oun ti n sunmo.
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ku si ilu Madina ni ojo aje (monday) ti se ojo kejila ninu osu keta osu elesin Islam (Rabu' l awwal) ni odun kokanla leyin Hijira. won si sin si ilu Madina. Ajalu nla ni iku Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) je fun awon musulumi, debi wipe awon kan ninu awon omoleyin re ko gba pe ododo ni pe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) papoda, ninu awon wonyi ni Umar omo Khatab (Olohun ko yonu si), o sope '' enikeni ti o ba sope Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti ku, ma so ori re kale. Abu bakri (Olohun ko yonu si) lowa dide ti o si ka oro Olohun to sope:
[وَمَا مُحَمَّدٌ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِ الرُّسُلُ أَفَإِنْ مَاتَ أَوْ قُتِلَ انْقَلَبْتُمْ عَلَى أَعْقَابِكُمْ وَمَنْ يَنْقَلِبْ عَلَى عَقِبَيْهِ فَلَنْ يَضُرَّ اللَّهَ شَيْئًا وَسَيَجْزِي اللَّهُ الشَّاكِرِينَ (144) ] .  
     '' (Anabi) Muhammad ko je nkaakan ju ojise lo, awon ojise ti wa siwaju re. se ti o ba ku tabi won ba pa e o yeyin pada ni bi? Enikeni ti o ba yeyin pada ko se ipalara kankan fun Olohun, Olohun yoo si san esan rere fun awon oludupe fun un'' Q3:144.
     Nigba Umar gbo awon ese oro wonyi ara re bale, o si je enikan ti ki koja ase Olohun.
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) papo da ni omo odun meta le logota. O lo ogoji odun ni ilu Makkah siwaju ki o to di Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba). Leyin ti o di anabi Olohun o lo odun metala ti o fi npe awon eniyan sibi imo Olohun lokan soso ni ilu Makkah. Leyin naa ni o se irin ajo esin (Hijira) lo si ilu Madina, o si lo odun mewa nibe. Al Quran so kale fun diedie titi ti o fi di odidi ti ofin esin si di pipe.
      Dr. G. Lebanon so ninu iwe re: ''olaju iran larubawa'': ti o ba jepe ise awon eniyan ni a fi n mo eniyan pataki, Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je okan pataki ninu awon eekan ninu itan omoniyan. Awon onimimo iran larubawa je oni deede nibi riroyin re. bi o tile jepe eleyameya esin di opolopo awon olukotan loju lati so ododo nipa ola ati ipo ti n be fun''.

AWON IROYIN RE
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) je eni ti o sigbonle, ti eyin re si fe. Irun re gun de ibi eti re. o rewa pupo o si dara ni eda. Ko ga rororo ko si kuru mole. Ko funfun gboo, ko si dudu rara. Irun re ko takoko mo ara won, ko si gun lojolojo. Oju re rewa pupo o si dabi omi aro goolu. Ara re mo fonifoni ti si ma n tan bi imole. Irungbon re po.
وسئل جابر بن سمرة -رضي الله عنه -: هل وجهه مثل السيف ؟ فقال: ( بل كان مثل الشمس والقمر وكان مستديراً )
      Won bi Jabir omo Samra wipe '' nje se bi ida ni oju re ri bi? O si dahun wipe ''rara, oju re da bi oorun ati osupa ti o se roboto'' (Muslim) enu re wa ni iwotun wonsi, egbe oju re si fe die, eran gigise re si kere. O lara ni iwontun wonsi, ko sanra berekete ko si tinrin pelebe. Owo ati ese re mejeji tobi die atelewo re na si fe.
قال أنس - رضي الله عنه -: (ما مسست حريراً ولا ديباجاً ألين من كف النبي ﷺ ولا شممت مسكاً ولا عنبراً أطيب من رائحة رسول الله ﷺ ).
     Anas (Olohun ki o yonu si) sope '' mi o fowo kan aso aran tabi siliki ti o wa le lowo bi owo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba), bakan naa mi o gbo oorun (lofinda) al misiki tabi anbari ti o wa ni oorun didun bi oorun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba). (Al Bukhari ati Muslim).

Die Ninu Awon Iwa, Iroyin Ati Adamo Re
1, Pipe ni Lakaye
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) mu ipo kan ti enikan ko mu ri nibi pipe lakaye. Al Qadi I'yadh sope: '' bi lakaye re sepe ati bio se mu berere yo ma han kedere si gbogbo eni ti o wadi isemi ati itan re. ti o si tun mo nipa awon oro gbankogbi ti o ma nso, ati adamo eleyin ati awon iroyin re ti ko legbe, ati awon oye ti oro re ati imo re ko sinu, inu awon iwe Taoreta, injila ati awon iwe ti o so kale lati oke sanmo, ati iwe ogbon awon amoye, iwe itan awon iran ti o ti koja, awon owe, iselu awon ijo ijo, awon iwe idajo ati ofin, awon iwe isagbekale ilana eko ije omoluwabi, ati iwe adamo eleyin titi ti o fi de ori awon iwe imo orisirisi ti awon ojogbon ti sa oro re ni esa.
      Awokose ni o je nibi gbogbo oun ti omoniyan ni bukata si, fun apere: abala ijosin, imo itoju alaisan, imo isiro, ogun pinpin, imo nipa iran ati beebee lo. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) imo awon nkan wonyi lai keko lodo enikan tabi ni ile eko, bakan naa ko ka iwe awon ti o ti wa siwaju re ko si joko pelu awon onimimo! Anabi ti ko le ko tabi ka titi ti Olohun fi sipaya emi re. Olohun fi ise han pelu pe o ko ni mimo o si mu ma ka. Bi lakaye re se to naa ni imo re se to ni abala awon oun ti Olohun fi mo ninu imo awon oun ti yoo sele ati awon ti o ti sele siwaju. Ninu ariyanu agbara Olohun ati titobi ola Re ni eleyi. (Shifa bita'reef huquuqi Al Mustapha).
2, Agbamora Ati Ireti Esan Lodo Olohun
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) je asiwaju nibi iroyin yi. O se alaba pade awon orisirisi inira ni oju ona ipepe soju ona olohun, o farada o si se suru ni eni ti n reti esan lodo Olohun. Abdullah omo Masu'd (Olohun ko yonu si) sope:
: كأني أنظر إلى رسول الله ﷺ يحكي نبياً من الأنبياء ضربه قومه - وهو يمسح الدم عن وجهه - ويقول:" اللهم اغفر لقومي فإنهم لا يعلمون "
     '' o dabi wipe mo n wo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) bayi nigba ti o n so nipa anabi kan ninu awon anabi Olohun ti awon ijo re dawo lu ti o si n nu eje loju re, ti o si nso bayi pe '' olohun forijin awon ijo mi toripe won ko mo'' (Al Bukhari ati Muslim). Jundub omo Sufyan (Olohun ko yonu si) sope:
: دَمِيتْ إصبع رسول الله ﷺ في أحد المشاهد فقال:(هَلْ أَنْتِ إِلاَّ إِصْبَعٌ دَمِيتِ وَفِي سَبِيلِ اللهِ مَا لَقِيتِ)
     '' okan ninu awon omo ika Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) n yo eje nibi okan ninu ogun, o si so bayi pe '' nje o wa ju ika lo ni bi، ti o n yo eje latara oun ti o ba pade ni oju ona Olohun'' (Al Bukhari ati Muslim).
3, Ise Afomo Ise fun Olohun
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) je enikan ti ma n se afomo gbogbo alamori re fun Olohun. Olohun ti ola re ga so bayi pe:
 [قُلْ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ (162) لَا شَرِيكَ لَهُ وَبِذَلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ (163)]
     '' wipe: dajudaju irun mi ati pipa eran se esin mi ati igbesi aye mi ati oku mi fun Olohun ni, Olohun gbogbo eda \\ ko si orogun fun. Eyi ni a pa mi lase re, emi si ni asiwaju awon olugbafa (fun Olohun) Q6: 162&163.
4, Iwa Rere Ati Ibagbepo Ti o Dara
      Aisha (Olohun ko yonu si) ti o je iyawo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) dahun nigba ti won bi leere nipa iwa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) wipe:
"كان خلقه القرآن "
     '' iwa re ni Al kurani '' (Al Musnad). itumo re nipe: o ma n tele ase olohun o si ma n jinna si awon oun ti Olohun ko, o si je apejuwe fun awon iroyin eleyin ti o wa ninu re, o si je eni ti o ma n jinna si awon oun ti Olohun ko ninu gbogbo iwa ibaje, eyi ti o foju han tabi eyi ti o pamo. Eleyi ko je iyalenu, toripe oun lo sope:
:" إِنَّمَا بُعِثْتُ لِأُتَمِّمَ مَكَارِمَ الْأَخْلَاقِ "
     '' dajudaju oun ti won tori re gbe mi dide (ni ojise) ni lati wa pe awon iwa eleyin'' (Muslim). Olohun ti ola Re ga royin re wipe:
[وَإِنَّكَ لَعَلَى خُلُقٍ عَظِيمٍ].
     '' atipe dajudaju ire je eniti o ni iwa ti o dara julo'' Q68:4.
      Anas omo Malik (Olohun ko yonu si) sope: oun gbe ni odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) fun odun mewa, losan ati loru, ni ile ati ni irin ajo, nitori idi eyi oun mo isesi ati ihuwasi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba)
"كان رسول الله ﷺ أحسن الناس خلقاً".
     '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ni eni ti o dara julo ni iwa'' (Al Bukhari ati Muslim). O tun so wipe:
لم يكن النبي ﷺ سباباً ولا فحاشاً ولا لعاناً، كان يقول لأحدنا عند المعتبة:" ما له ترب جبينه"
     '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ki se eni ti ma n bu eebu, tabi so oro ibaje, tabi eni ti o ma se epe, o ma n so nigba ti o ba fe bawa wi '' ki lo se eleyi ti o nfi iwaju re gbole ti osi lapa pelu erupe?'' (Al Bukhari).
5, Ise Omoluwabi
      Sahl omo Sa'd (Olohun ko yonu si) sope:
أن رسول الله ﷺ أتي بشراب فشرب منه وعن يمينه غلام وعن يساره الأشياخ، فقال للغلام:" أتأذن لي أن أعطي هؤلاء ؟ " فقال الغلام: والله يا رسول الله لا أوثر بنصيبي منك أحداً، قال: فتله - وضعه - رسول الله ﷺ في يده "
      '' won gbe oun mimu wa fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) o si mu nibe. Odomode kan n be ni egbe otun re nigba ti awon agbalagba si wa ni egbe osi re, o wa so fun odomode yi pe '' se o yonda fun mi ki n gbe fun awon agbalagba wonyi? Odomode naa si dahun wipe '' mo fi Olohun bura, ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) mi o le yonda ki enikan gba ipo mi lodo re. Ojise Olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) si gbe le lowo'' (Al Bukhari ati Muslim)
6, Iferan Atunse
      Sahlu omo Sa'd (Olohun ko yonu si) sope: ''awon ara Quba n ba ara won ja, ti won si bere si ni le ara won ni okuta. Oro yi de etigbo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) o si so bayi pe:
"اذهبوا بنا نصلح بينهم "
     '' e je ki a lo se atunse laarin won'' (Al Bukhari).
7, Ipase Dada Ati Kiko Iwa Ibaje
      Abdullah omo Abas (Olohun ko yonu si awon mejeeji) sope: Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ri oruka golu ni owo arakunrin kan, o fa yo, o si so bayi pe:
 " يعمد أحدكم إلى جمرة من نار فيجعلها في يده " فقيل للرجل بعدما ذهب رسول الله صلى الله ﷺ ، خذ خاتمك انتفع به، قال: لا والله لا آخذه أبداً وقد طرحه رسول الله ﷺ ".
      '' enikookan ninu yin yoo ma lo si ibi eye ina, yoo si fi si owo re'' awon kan so fun arakunrin yi ki o lo mu orika re leyin ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ti lo, o si dahun wipe rara, mo fi Olohun bura wipe mi o ni mu lailai leyin igba ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ti so nu'' (Muslim)
8, Imototo
      Al Muhajir omo Qanfadh (Olohun ko yonu si) so pe oun wa ba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ko moo ba) ni asiko ti o n to lowo oun si salama si ko dahun titi ti o fi se aluwala. Leyin naa lo ni ki o ma binu, o si sope:
:" إني كرهت أن أذكر الله عز وجل إلا على طهر أو قال على طهارة ". (سنن أبي داوود)
     '' mo korira ki n daruko Olohun ti ola re ga ayafi pelu imora tabi nigba ti mo ba wa ni imora'' (Abu DAwud)
9, Ima So Ahon (Enu)
     Abdullah omo baba Aofa sope:
"كان رسول الله ﷺ يكثر الذكر ويقل اللغو ويطيل الصلاة ويقصر الخطبة, ولا يأنف أن يمشي مع الأرملة أو المسكين فيقضي حاجته".
     '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ma n ranti Olohun pupo, o kere ni awada, irun (kiki) re ma n gun, ibanisoro (khutuba) re si ma n kere, ko ki n se igberaga nibi ririn pelu opo tabi alaini lati gbo bukata re'' (An nasai).
10, Ijosin Fun Olohun Lopolopo
         Aisha (Olohun ko yonu si) sope:
" أن نبي الله ﷺ كان يقوم من الليل حتى تتفطر قدماه, فقالت عائشة: لم تصنع هذا يا رسول الله! وقد غفر الله لك ما تقدم من ذنبك وما تأخر ؟. قال:" أفلا أحب أن أكون عبدا شكورا "
      '' dajudaju Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ma n ji kirun ni oru titi ti ese re fi wu, Aisha (olohun ko yonu si) wa sope: ki lo de ti o n se eleyi ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ! se bi Olohun ti se aforijin ese ti o da siwaju ati eyi ti o tun da? O si da lohun wipe '' se ko wa ye ki n je eru ti yoo ma dupe fun olohun'' (Al Bukhari ati Muslim)
11, Pelepele Ati Irorun
     Abu Hurayra (Olohun ko yonu si) sope: Tufayl omo A'mru Ad dawsi ati awon omoleyin re wa si odo ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) won si sope ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)
 "إن دوساً عصت وأبت فادعوا الله عليها. فقيل هلكت دوس، فقال النبي ﷺ:" اللهم اهد دوساً وأت بهم "
     '' dajudaju awon iran Daws won yapa won si ko, se epe fun won. Awon kan ni awon iran Daws ti parun, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun pe '' ire olohun fi ona mo iran Daws ki o si mu won wa''(Al Bukhari ati Muslim)
12, Didara Laworan
     Barau omo A'zib (olohun ko yonu si) sope:
"كان النبي ﷺ مربوعاً بعيد ما بين المنكبين, له شعر يبلغ شحمة أذنيه, رأيته في حلة حمراء لم أر شيئا قط أحسن منه ".
     Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti o sigbonle, ti eyin re si fe. Irun re gun de ibi eti re, mo ri ti o wo aso pupo kan, mi o ri oun ti o dara ju (anabi) lo ri''(Al Bukhari ati Muslim)
13, Iri Aye Sa (Mimu Aye Kekere)
 Abdullah omo Masu'd (olohun ko yonu si) sope: ojise olohun (ike ati ola olohun ko moo ba) sun lori eni, nigba ti o dide eni ti fa ila si lara, a wa sope ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)
 " لَوْ اتَّخَذْنَا لَكَ وِطَاءً. فَقَالَ: مَا لِي وَلِلدُّنْيَا؟ مَا أَنَا في الدُّنْيَا إِلاَّ كَرَاكِبٍ اسْتَظَلَّ تَحْتَ شَجَرَةٍ ثُمَّ رَاحَ وَتَرَكَهَا "
    '' ki lo de ti o wa ite ti o rewa fun o, o si dahun wipe ki lo pa emi ati ile aye po? Apejuwe mi nile aye da bi eni ti o gun nkangun ti o wa sinmi labe iboji igi (fun igba kekere) ti o si gbera pada ti o fi iboji igi naa sile'' (At tirmidhi).
     A"mru omo Al Harith (Olohun ko yonu si) sope:
 "ما ترك رسول الله ﷺ عند موته درهماً ولا ديناراً ولا عبداً ولا أمةً ولا شيئاً إلا بغلته البيضاء وسلاحه وأرضاً جعلها صدقةً".
      '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ko fi nkankan sile nigba ti o kuro laye yala owo ni tabi eru lokurin tabi lobinrin ayafi ibaka re funfun ati awon nkan ija ogun pelu ile ti o fi se sara'' (Al Bukhari).
14, Gbigbe Ola Fun Elomiran
     Sahl omo Sa'd (Olohun ko yonu si) sope:
 عن سهل بن سعد رضي الله عنه قال: جاءت امرأة ببردة قال: أتدرون ما البردة؟ فقيل له: نعم هي الشملة منسوج في حاشيتها. قالت يا رسول الله: إني نسجت هذه بيدي أكسوكها، فأخذها النبي ﷺ محتاجا إليها, فخرج إلينا وإنها إزاره, فقال رجل من القوم: يا رسول الله اكسنيها فقال:" نعم" فجلس النبي في المجلس ثم رجع فطواها, ثم أرسل بها إليه فقال له القوم: ما أحسنت سألتها إياه, لقد علمت أنه لا يرد سائلا ! فقال الرجل: والله ما سألته إلا لتكون كفني يوم أموت. قال سهل فكانت كفنه.
     Arabinrin kan mu aso Burda wa, o sope: '' nje e mo oun ti n je Burda? Won dahun wipe bee ni: aso ibora ti won hun lati ibi irun eran ti won si hun eteeti re. obinrin naa sope ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) '' mo hun aso yi fun ra mi lati fun ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gba ni eni ti o ni bukata si, o si jade si wa leni ti o ro aso naa, arakunrin kan ninu awon to wa nibe ba sope: '' ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fun mi ni aso yi, o si dahun wipe ''ma fun e'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) joko si ijoko re leyin naa o dide o si ka aso naa, o si fi ranse si arakunrin naa. Awon ti o wa nibe si so bayi pe '' ibeere re yi ko dara rara, nigba ti o ti mo pe ko ni salai mo fi oun ti won ba beere lowo re sile! Okunrin naa si dahun wipe '' mo fi Olohun bura pe mi o beere bikosepe ki o le jepe oun ni won yoo fi sin mi nigba ti mo ba ku. Sahl sope oun naa ni won si fi sin'' (Al Bukhari).
15, Agbara Igbagbo Ododo Ati Igbarale Ninu Olohun
     Abu Bakri (Olohun ko yonu si) olododo sope:
"نظرت إلى أقدام المشركين على رؤوسنا ونحن في الغار فقلت: يا رسول الله! لو أن أحدهم نظر إلى قدميه أبصرنا تحت قدميه، فقال: "يا أبا بكر ما ظنك باثنين الله ثالثهما"
     '' nigba ti mo ri gigise awon osebo loke wa nigbati ti a wa ninu koto, mo sope ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti enikan ninu won ba le wo abe ese re, yoo ma ri wa!!!, osi dahun wipe '' ire Abu Bakri kin ni ero re nipa awon eniyan meji ti olohun je eleeketa won' '(Al Bukhari ati Muslim)
16, Ike Ati Anu
     Abu Qatadah (Olohun ko yonu si) sope:
"خرج علينا رسول الله ﷺ وأمامة بنت أبي العاص على عاتقه فصلى فإذا ركع وضعها وإذا رفع رفعها ".
     '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) jade si wa o si gbe umamatu omo Abu al Aas si ejika, o si kirun be, ti o ba ruku yoo gbe sile ti o ba si dide yoo gbe dani'' (Al Bukhari ati Muslim).
17, Sise Irorun
     Anas (Olohun ko yonu si) sope, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
"إني لأدخل في الصلاة وأنا أريد إطالتها فأسمع بكاء الصبي فأتجوز في صلاتي مما أعلم من شدة وجد أمه من بكائه ".
      '' igba miran ma wo inu irun ni eni ti o fe fa irun gun, sugbon ti mo ba ti gbo ohun omokekere ma se kiakia nibi irun mi nitori inira ti o le ma ba iya latara omo re ti o n ke'' (Al Bukhari).
18, Ipaya Olohun Ati Nini Asaje
     Abu Hurayra (Olohun ko yonu si) sope, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إني لأنقلب إلى أهلي فأجد التمرة ساقطة على فراشي فأرفعها لآكلها، ثم أخشى أن تكون صدقة فألقيها.".
     '' mo ma n lo si odo ara ile mi nigba miran ti ma si ri eso tamaru ti o jabo si ori ibusun mi, ma mu lati je, sugbon ma fi sile nigba ti mo ba ro pe o le je ore (saara) (Al Bukhari ati Muslim).
19, Ima Nawo
     Anas omo Malik (Olohun ko yonu si) sope:
"ما سئل رسول الله ﷺ على الإسلام شيئا إلا أعطاه ﷺ قال فجاءه رجل فأعطاه غنما بين جبلين فرجع إلى قومه فقال: يا قوم أسلموا, فإن محمدا ﷺ يعطي عطاء لا يخشى الفاقة".
     '' won ko ni toro nkankan lowo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nitori Islam ayafi ki o fun onitohun. O sope arakunrin ke de o si fun ni eran agutan ti o le kun aarin oke meji, o pada si odo awon eniyan re o si sope: '' eyin eniyan mi eyin naa e di musulumi, toripe dajudaju (Anabi) Muhammad n ta ore ti o si  beru osi'' (Muslim).
20, Iferan Iranlowo Ati Ifowosowopo
     Aisha (Olohun ko yonu si) dahun nigba ti won bi wipe
"ما كان النبي ﷺ يصنع في بيته ؟ قالت: كان يكون في مهنة أهله فإذا حضرت الصلاة خرج إلى الصلاة. "
     '' kin ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ma n se ninu ile? O dahun wipe o ma n ran awon ara ile re lowo, ti asiko irun ba si to yoo lo kirun'' (Al Bukhari).
     Barau omo A'zib sope:
"رأيت النبي ﷺ يوم الخندق وهو ينقل التراب حتى وارى -غطى - التراب شعر صدره, وكان رجلا كثير الشعر وهو يرتجز برجز عبد الله بن رواحة:" اللهم لولا أنت ما اهتدينا - ولا تصدقنا ولا صلينا - فأنزلن سكينة علينا - وثبت الأقدام إن لاقينا - إن الأعداء قد بغوا علينا - إذا أرادوا فتنة أبينا " يرفع بها صوته.
     '' mo ri Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni asiko ogun Koto giriwo (Khandaq) ti n gbe yerupe titi ti yerupe fi bo irun igbaaya re, o si je eni ti irun po lara re, o si n gbe orin ti Abdullah omo Rawahah nko bayi pe '' ti ki ba se anu re a ba ti mo ona (Islam) \\ a ba ti ta ore (zakah) a ba si ti ki irun \\ so ifokanbale le wa lori \\ ki o si fi ese wa rinle ni oju ogun \\ awon ota ti se abosi wa \\ won si gbero lati fi suta kan baba wa \\, ni eni ti n gbe ohun soke. (Al Bukhari ati Muslim).
21, Ododo Siso
     Aisha (Olohun ko yonu si) sope:
 "ماكان خلق أبغض إلى رسول الله ﷺ من الكذب، ولقد كان الرجل يحدث عند رسول الله بالكذبة، فما يزال في نفسه حتى يعلم أنه قد أحدث منها توبة"
     '' ko si oun ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) korira bi iro pipa, enikan ko ni pa iro ni odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ayafi ki eni naa wa lori emi re titi ti yoo fi mo pe o ti ronupiwada'' (At tirmidhi).
      Awon ota Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) paapaa jeri lori pe olododo ni. Abu Jahl ti o je okan pataki ninu awon ota re so fun ni ojokan pe '' ire Muhammad, mi o so pe opuro ni o rara, sugbon oun ti o mu wa ti o n pepe lo sibe ni mo n tako. Bayi ni olohun ti ola re ga so oro re kale bayi pe:
    [ قَدْ نَعْلَمُ إِنَّهُ لَيَحْزُنُكَ الَّذِي يَقُولُونَ فَإِنَّهُمْ لَا يُكَذِّبُونَكَ وَلَكِنَّ الظَّالِمِينَ بِآيَاتِ اللَّهِ يَجْحَدُونَ (33)] .( الأنعام:33)
     '' dajudaju awa ti mo pe ohun ti won nso si o yoo ba o ninu je, dajudaju awon naa ko le pe o ni opuro, sugbon awon alabosi nse atako si awon ami Olohun'' Q6:33.
22, Pipataki Iwo Olohun
     Aisha (Olohun ko yonu si) sope:
"ما خير النبي ﷺ بين أمرين إلا اختار أيسرهما ما لم يأثم (أي ما لم يكن إثما) فإذا كان الإثم كان أبعدهما منه والله ما انتقم لنفسه في شيء يؤتى إليه قط حتى تنتهك حرمات الله فينتقم لله".
     '' won o yonda fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pe ki o se esa laarin nkan meji ayafi ki o se esa eyi ti o rorun julo nigba ti ki ba se ese, ti o ba je ese ni oun ni yoo je eni ti yoo jina si julo, mo fi Olohun bura wipe ko gbesan nitori ara re lori eyikeyi nkan ti won ba se fun ri, ayafi igba ti o ba je iwo Olohun, yoo gbesan nitori Olohun'' (Al Bukhari ati Muslim).
23, Ima Tujuka
     Abdullah omo Al Harith (Olohun ki o yonu si) sope:
"ما رأيت أحداً أكثر تبسماً من رسول الله ﷺ." (سنن الترمذي)
      '' mi o ri enikan ti o po ni irerin muse bi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)'' (At tirmidhi).
24, Ini Agbekele Ati Pipe Adehun
     Iwa igbekele re je okan ti ko legbe. Awon ara Makkah ti won mu ni ota leyin igba ti o bere ipepe re, ti won si fi inira orisirisi kan oun ati awon omoleyin re. pelu be won ko ye gbe awon dukia ati gbafipamo won pamo si lodo. Nigba ti o di pe o fe se Hijirah lo si ilu Madina lati ara inira ti won fi nkan ni ilu Makkah. O pa Ali omo Abu Talib (Olohun ki o yonu si) lase ki o duro si Makkah lati da awon dukia ati gbafipamo awon ara Makkah pada laarin ojo meta. (Ibn Hisham)
 Bakan naa ninu apere pipe adehun re: nigba ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ati Suhayl omo A'mru fe ko iwe adehun ni ojo Hudaybiyah lori asiko, ninu awon oun ti Suhayl omo A'mru se ni mojemu fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni pe '' enikeni ninu awon eniyan wa (ko ba je musulumi) ti o ba wa si odo re o gbudo da pada si odo wa, ki a si se oun ti o ba wu wa le lori. Suhayl ko jale fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ayafi pelu mojemu yi. Inu awon musulumi ko dun si eleyi rara, o si le ni ara won, won si so oro ni ori re. sugbon nigba ti Suhayl ko jale ayafi pelu mojemu yi Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gba fun un. Laarin igba yi ni Abu Jundul omo Suhayl omo A'mru wole ni eni ti n wo rin latara oun ti won so mo lese. O wo jade lati isale Makkah titi ti o fi subu si aarin awon musulumi. Suhayl omo A'mru ti o je baba Abu Jundul sope '' ire Muhammad, eleyi ni yoo je eni ti o yonda fun mi'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dahun wipe '' yonda re fun mi'' o si dahun pada pe '' mi o le yonda re fun o'' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) tun sope '' o yonda re'' o si tun dahun wipe '' mi o le se be''. Abu jundul fura mo ohun ti nsele, o si beere ni owo awon musulumi pe '' eyin musulumi, se ma pada si odo awon osebo leyin igba ti mo wa ba yin ni musulumi? Se e o ri oun ti o sele si mi ni? Won fi iya ti o ni agbara je mi nitori Olohun. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) da pada si odo Suhayl omo A'mru lati pe adehun ti o jo wa laarin won. (Al Bukhari).
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun Abu Jundul
:" يَا أبا جندل اصبر واحتسب, فإن الله جاعل لك ولمن معك من المستضعفين فرجاً ومخرجاً, إنا قد صالحنا هؤلاء القوم وجرى بيننا وبينهم العهد وإنا لا نغدر"
     '' ire Abu Jundul se suru ki o si ma reti esan re lodo Olohun, dajudaju Olohun yoo se ona itusile ati abayo fun iwo ati awon ti o wa pelu re ninu awon ole, ati gbe adehun atunse pelu awon eniyan wonyi, adehun si ti wa laarin wa, awa o si ninu eni ti ma nye adehun'' (Musna Ahmad).
      Leyin yi ni Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pada si ilu Madina. Abu Basheer, ti o je okan ninu awon Qurayshi sugbon ti o di musulumi, de si Madina. Won ran awon meji lati wa lo si Madina, won si fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pe '' adehun ti o se fun wa?'' ojise olohun si fa lewon lowo.
25, Ije Akin Ati Ini Ipinnu
     Ali omo Abu Talib (Olohun ki o yonu si) sope
"لقد رأيتني يوم بدر ونحن نلوذ (نحتمي) بالنبي ﷺ وهو أقربنا إلى العدو وكان من أشد الناس يومئذ بأساً". (مسند الإمام أحمد)
     '' ni ojo ogun Badr mo ri pe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni a fi se idabobo, oun ni o sunmo awon ota ju ninu wa, oun ni o si le ju (ni oju ogun) ni ojo yi (Musnad Ahmad).
     Igboya ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) yato si oju ogun, Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
 "كان النبي ﷺ أحسن الناس وأشجع الناس ولقد فزع أهل المدينة ليلة فخرجوا نحو الصوت فاستقبلهم النبي ﷺ وقد استبرأ الخبر وهو على فرس لأبي طلحة عري وفي عنقه السيف وهو يقول: "لم تراعوا لم تراعوا. ثم قال: وجدناه بحرا أو قال إنه لبحر "
     '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti o dara julo ninu eniyan, o si je eni ti o ni igboya julo. Ni ale ojo kan ipaya de ba awon ara Madina, gbogbo won si jade lati lo si ibi ti ohun naa ti n wa, sugbon Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni won pade lati ona ibe, o ti wadi oun ti n sele, o gun esin Abu Taliha lai mu ina dani, o fi ida ko orun, o si n so bayi pe '' ko si ifoya, ko si ifoya'' o si sope '' a ri pe (esin) na n sare pupo'' (Al Bukari ati Muslim).
      Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se eleyi lati fi awon ara Madina lokan bale, bakan naa o tete dide si oro naa toripe oro ko gba ki o duro de enikankan atipe esin ti o gun nsare pupo.
      Ni ojo ogun Uhud, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se imoran pelu awon omoleyin re (Olohun ki o yonu si won) won si gba ni imoran ki o je ki awon lo si ogun, nigba ti o si jepe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gbero nkan miran sugbon o gba irori won. Awon omoleyin re kabamo lori pe awon gbero oun ti o yato si erongba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Awon Ansar (ara Madina) si sope '' a ko gba irori Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)! Won si lo si odo re won si so bayi pe '' ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je ki a se oun ti o gbero'' o si dahun wipe
" إنه ليس لنبي إذا لبس لامته [الدرع وآلة الحرب] أن يضعها حتى يقاتل "
     '' ko leto fun Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o ti wo aso ogun ki o bo sile titi ti yoo fi jagun'' (Musnad Ahmad).
26, Ore Tita
Omo Abas (Olohun ki o yonu si won) sope:
يقول ابن عباس رضي الله: "كان رسول الله ﷺ أجود الناس, وكان أجود ما يكون في رمضان حين يلقاه جبريل, وكان يلقاه في كل ليلة من رمضان فيدارسه القرآن, فلرسول الله ﷺ أجود بالخير من الريح المرسلة".
     '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni olutore ju ninu awon eniyan, ore tita re si tun ma n lekenka ninu (osu) Ramadhan nigba ti Jubril ma n pade pelu re, o ma pade re ni gbogbo ale ninu Ramadhan ti yoo si ko ni Al Quran, ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ma n tore ju ategun ti n fe lo'' (Al Bukari ati Muslim).
      Abu Dharri sope '' mo nlo pelu Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni adugbo kan ninu ilu Madina, a ba pade enikan, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun pe
" يا أباذر " قلت: لبيك يا رسول الله، قال:" ما أحب أن أحدا لي ذهبا يأتي علي ليلة أو ثلاث عندي منه دينار إلا أرصده لدين إلا أن أقول به في عباد الله هكذا وهكذا وهكذا" عن يمينه وعن شماله ومن خلفه".
     '' ire Abu Dharri, mo dahun wipe '' mo n dahun ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)'' '' ko le dun mo mi kin ni golu ti o dabi oke uhud, ki n wa lo ale kan tabi ojo meta ki Dinar kan si seku si odo mi ti ki se eyi ti mo seku lati fi san gbese, ayafi ki n na fun awon eru olohun bayi bayi bayi, lotun losi ati leyin'' (Al Bukari ati Muslim).
     Jabir omo Abdullah (Olohun ki o yonu si) sope:
 "ما سئل النبي ﷺ عن شيء قط فقال: لا".
     '' won o toro nkan lowo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ri ko wa sope kosi'' (Al Bukari ati Muslim).
27, Ojuti
      Abu saee'd Al khudri (Olohun ki o yonu si) sope:
 يقول أبو سعيد الخدري رضي الله عنه: "كان النبي ﷺ أشد حياءً من العذراء في خدرها، فإذا رأى شيئاً يكرهه عرفناه في وجهه. "
     '' Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti o ni ojuti ju omoge ninu gaga re lo. Ti o ba ri oun ti o korira, oju re ni a ti ma n mo'' (Al Bukari ati Muslim).
28, Ire ra eni sile.
     Dajudaju Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eniti o re ara re sile julo ninu omoniyan. Ire-ra-eni-sile re ni agbara debi wipe ti eni ti ko ba mo ri tele ba wo masalasi ko ni da mo yato laarin awon omoleyin re. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
 "بينما نحن جلوس مع النبي ﷺ في المسجد دخل رجل على جمل فأناخه في المسجد ثم عقله, ثم قال لهم: أيكم محمد؟ والنبي ﷺ متكئ بين ظهرانيهم, فقلنا: هذا الرجل الأبيض المتكئ..."
     ''laarin igba ti a joko pelu Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni inu masalasi, okunrin kan ti o gun rakunmi wole o si da kunle si inu masalasi leyin naa o si so mole, o wa beere wipe '' tani Muhammad ninu yin? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si rogbokun si aarin awon omoleyin re, a wa dahun wipe '' okunrin funfun ti o rogbokun….. (Al Bukhari).
     Ki se igberaga tabi ijo ara eni loju lati rin pelu awon alaini, ole tabi eni ti o ni bukata lati gbo bukata won. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
أن امرأة من أهل المدينة كان في عقلها شيء، فقالت يا رسول الله: إن لي إليك حاجة، فقال:" يا أم فلان انظري أي السكك - الطرق - شئت، حتى أقضي حاجتك "فخلا معها في بعض الطرق حتى فرغت من حاجتها ". (صحيح مسلم)
     Arabinrin kan ninu awon ara Madina, ti o ni arun opolo, sope ''ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), mo ni bukata si o'' o si da lohun pe '' iya lagbaja wo eyikeyi ona ti o ba fe ki n ti wa ri o, titi ti ma fi gbo bukata re'' o si dide tele arabinrin yi lo si ibi ti o fe titi ti o fi gbo bukata re. (Muslim).
29, Anu Ati Ike.
     Abu Masu'd Al ansari (Olohun ki o yonu si) sope:
 "جاء رجل إلى النبي ﷺ فقال: يا رسول الله، إني والله لأتأخر عن صلاة الغداة من أجل فلان مما يطيل بنا فيها، قال: فما رأيت رسول الله ﷺ قط أشد غضباً في موعظة منه يومئذ، ثم قال:" أيها الناس إن منكم منفرين فأيكم ما صلى بالناس فليوجز، فإن فيهم الكبير والضعيف وذا الحاجة " (صحيح البخاري ومسلم)
     '' arakunrin kan wa si odo ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) o si sope '' ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), mofi Olohun bura pe dajudaju mo mo n pe wa ki irun asunba (afemoju) nitori lagbaja ti o ma n pe lori irun, o sope mi o ri ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki o binu to bayi ri nigba ti o ba nse isiti (waasi) gege bi ti ojo yi, leyin naa ni o so pe '' eyin eniyan, o n be ninu yin eni ti n le awon eniyan (nibi irun) eyikeyi ninu yin ti o ba ki irun fun awon eniyan ki o ya se ni fufuye, toripe dajudaju o n be ninu won agbala, ole ati eni ti o ni bukata'' (Al Bukari ati Muslim).
     Usamah omo Zayd (Olohun ki o yonu si) sope:
 كنا عند النبي ﷺ إذ جاءه رسول إحدى بناته تدعوه إلى ابنها في الموت. فقال النبي:"ارجع فأخبرها أن لله ما أخذ وله ما أعطى, وكل شيء عنده بأجل مسمى, فمرها فلتصبر ولتحتسب" فأعادت الرسول أنها أقسمت لتأتينها, فقام النبي وقام معه سعد بن عبادة ومعاذ بن جبل فدفع الصبي إليه ونفسه تقعقع (تضطرب) كأنها في شن (قربة الماء) ففاضت عيناه, فقال له سعد: يا رسول الله ما هذا؟ قال:"هذه رحمة جعلها الله في قلوب عباده وإنما يرحم الله من عباده الرحماء" (صحيح البخاري وصحيح مسلم)
     A wa ni odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nigba ti iranse okan ninu awon omobinrin re wa pe fun omo re ti o poka iku lowo, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope '' pada ki o lo so fun wipe: Olohun ni o ni oun ti O mu, Oun ni o si ni oun ti O fun ni, gbogbo nkan ni o si ni asiko ni odo Re, so fun pe ki o se suru ki o si ma reti esan ni odo re'' iranse pada de pe o ni ki Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa ni, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dide, sa'd omo U'badah ati Maa'dh omo Jabal naa dide pelu re, won gbe omo naa fun ti emi re si ti nlo ti nbo, ojise da omije ni oju, Sa'd wa beere wipe ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) kin ni eleyi? O si dahun wipe '' eleyi ni aanu ti olohun ma nfi si okan awon eru re, dajudaju awon ti olohun ma nke ninu awon eru re naa ni awon ti won ma nke awon omoniyan'' (Al Bukari ati Muslim).
30, Ini Atemora Ati Amojukuro.
     Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
 "كنت أمشي مع النبي ﷺ وعليه برد (رداء) نجراني (من نجران باليمن) غليظ الحاشية فأدركه أعرابي فجذبه جذبة شديدة حتى نظرت إلى صفحة عاتق (جنب رقبة) النبي ﷺ قد أثرت به حاشية الرداء من شدة جذبته, ثم قال: يا محمد! مر لي من مال الله الذي عندك. فالتفت إليه فضحك ثم أمر له بعطاء".
     '' mo n lo pelu ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), o lo iro aso ti won se lati Najran ni ilu Yaman, eti aso naa nipan pupo. Larubawa oko kan ba ni oju ona, o si fa aso naa mo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lorun ti osi fun tagbara tagbara, nigba ti mo wo orun ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) eti aso naa ti fa ila si orun re latara fifun tagbara tagbara, leyin naa ni o so pe '' ire Muhammad! Pase ki won fun mi ninu owo Olohun ti n be ni odo re. o boju woo leni ti nrerin, o si ni ki won fun ni oun ti o fe. (Al Bukhari).
      Ninu awon apere atemora Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o ni agbara: oro nipa Zayd omo Saa'na ti o je okan ninu awon agba alufa elesin Yehuudi.
 
أنه أقرض النبي ﷺ قرضاً كان قد احتاج إليه ليقضي شؤون بعض المؤلفة قلوبهم. يقول زيد: فلما كان قبل محل الأجل بيومين أو ثلاثة خرج رسول الله ﷺ في جنازة رجل من الأنصار ومعه أبو بكر وعمر وعثمان ونفر من أصحابه, فلما صلى على الجنازة دنا من جدار فجلس إليه, فأخذت بمجامع قميصه ونظرت إليه بوجه غليظ ثم قلت: ألا تقضيني يا محمد حقي؟ فو الله ما علمتكم بني عبد المطلب بمطل ولقد كان لي بمخالطتكم علم!! قال: ونظرت إلى عمر بن الخطاب وعيناه تدوران في وجهه كالفلك المستدير ثم رماني ببصره, وقال: أي عدو الله! أتقول لرسول الله ﷺ ما أسمع, وتفعل به ما أرى, فو الذي بعثه بالحق لولا ما أحاذر فوته لضربت بسيفي هذا عنقك, ورسول الله ﷺ ينظر إلى عمر في سكون وتؤدة ثم قال:" إنا كنا أحوج إلى غير هذا منك يا عمر أن تأمرني بحسن الأداء, وتأمره بحسن التباعة - طلب الحق - اذهب به يا عمر فاقضه حقه, وزده عشرين صاعا من غيره مكان ما رعته" قال زيد: فذهب بي عمر فقضاني حقي وزادني عشرين صاعا من تمر, فقلت: ما هذه الزيادة ؟ قال: أمرني رسول الله ﷺ أن أزيدك مكان ما رعتك. فقلت: أتعرفني يا عمر ؟ قال: لا فمن أنت ؟ قلت: أنا زيد بن سعنة قال: الحبر؟ قلت: نعم الحبر. قال: فما دعاك أن تقول لرسول الله ﷺ ما قلت وتفعل به ما فعلت ؟ فقلت: يا عمر كل علامات النبوة قد عرفتها في وجه رسول الله ﷺ حين نظرت إليه إلا اثنتين لم أختبرهما منه: يسبق حلمه جهله, ولا يزيده شدة الجهل عليه إلا حلما, فقد اختبرتهما فأشهدك يا عمر أني قد رضيت بالله ربا وبالإسلام دينا وبمحمد ﷺ نبيا, وأشهدك أن شطر مالي فإني أكثرها - المدينة مالاً - صدقة على أمة محمد ﷺ, فقال عمر: أو على بعضهم فإنك لا تسعهم كلهم قلت: أو على بعضهم. فرجع عمر وزيد إلى رسول الله ﷺ فقال زيد: أشهد أن لا إله إلا الله, وأن محمدا عبده ورسوله ﷺ, فآمن به وصدقه وشهد مع رسول الله ﷺ مشاهد كثيرة, ثم توفي في غزوة تبوك, مقبلاً غير مدبر, رحم الله زيدا.
     O ya Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni owo fun bukata awon eniyan ti o fe fa oju won mora nitori esin. Zayd sope; nigba ti o ku ojo meji tabi meta ki ojo adehun lati san gbese pe, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pelu Abu Bakri, Umar, Uthman ati die ninu awon omoleyin re (Olohun ki o yonu si won), jade lati lo kirun si oku kan lara ninu awon Ansari. Nigba ti o kirun si oku lara tan, o sun mo ogiri o si joko. Mo fa orun aso re tagbara tagbara, mo si wo tika tegbin, mo si so bayi pe; se o ni san gbese mi fun mi ni ire Muhammad? mo fi olohun bura wipe mi o mo iran Abdul Mutalib si eni ti o ma lora lati san gbese, lai ni iyemeji ninu mo ti mo nipa yin latara ibayin sepo mi !! o sope; mo n wo Umar omo Khatab ni eni ti oju re mejeeji ti pon rokoso bi eye ina, leyin naa ni o wo mi tibinu tibinu ti o si sope; ire ota Olohun ! se Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) naa ni o n so awon oro buruku wonyi si, ti o si tun fa  aso mo lorun, mo fi eni ti o gbee dide pelu ododo bura, ti kii ba se ti oun ti mo n paya ki o ma bo, mi o ba si fi ida mi so ori re kale. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) n wo Umar pelu ifarabale ati iwoye, o si so bayi pe '' oun ti a ni bukata si ni odo re ju eleyi lo ire Umar. O ye ki o gba mi ni imoran ki n tete san gbese re, ki o si gba oun naa ni imoran ki o sin gbese re ni ona ti o dara. Ire Umar, mu u lo ki o si san gbese re fun. Ki o si fi ogun saahi' (osunwon ti eyokan re se deede mudu merin) kun fun latara eru ti o da ba'' Zayd sope; Umar mu mi lo, o si san gbese mi pelu alekun ogun saahi'. Mo wa beere wipe '' bawo ni ti ogun saahi' ti je? o si dahun wipe; ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni o ni ki n fi ogun saahi' kun un fun o tori eru ti mo da ba o. mo wa beere wipe; nje o mo mi ire Umar? o dahun wipe; rara, tani o? mo si dahun wipe; emi ni Zayd omo Saa'na. o beere wipe; alufa yehuudi? mo dahun wipe; beeni. O wa beere wipe; kin ni o ti o fa ti o fi so awon oun ti o so ati se awon isesi ti o se si Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)? mo si dahun wipe; ire Umar, gbogbo amin ije ojise olohun ni mo ti ri ni oju Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nigba ti mo wo oju re ayafi meji pere ni mi o ti se idanwo fun ni ori won: atemora ti o ni agbara ju aimokan lo, bakan naa isesi alaimokan ko ni leekun ju atemora lo. Bayi mo ti danwo lori mejeeji. Mo wa n fi o jeri ire Umar wipe; mo yonu si Olohun ni Oluwa, mo si yonu si Islam ni esin, mo si yonu si Muhammad ni anabi. Mo tun n fi o jeri wipe; dajudaju emi ni eni ti o ni dukia julo ni ilu Madina, mo fi idaji dukia mi tore fun gbogbo ijo Muhammad. Umar si dahun wipe; abi fun die ninu won, toripe itore re ko le kari gbogbo won. Mo si dahun wipe; fun die ninu won. Nigba ti Umar ati Zayd pada si odo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), Zayd si sope; mo jeri pe ko si eni ti o leto si ijosin ayafi Olohun atipe Muhammad je eru ati Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). O ni igbagbo si Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), o gba ni ododo, o si kopa ninu awon ogun pelu ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). O ku si oju ogun Tabuk (Olohun ki o yonu si). (ibn Hiban).
      Bakan naa ninu eyi ti o ga julo ninu awon apejuwe amojukoro re; oun naa ni igba ti o wo ilu Makkah ti o si segun. Won ko awon ara Makkah jo si inu masalasi, ninu awon ti won fi iran ran suta kan ti won si tun se okunfa lile jade ninu ilu re. o wa bi won leere wipe '' kin ni e ro wipe ma se fun yin?'' won si dahun wipe; daada ni, (toripe) o je omo iya alaponle ti o je omo alaponle. O si dahun wipe '' e maa lo, e ti di ominira'' (Al Bayhaqi).
31, Suru Sise
     Apejuwe ti o ga ni o je nibi suru sise. Siwaju ki o to bere ise ipepe o je onisuru lori awon oun ti awon eniyan re n se nise ati lori awon orisa ti won n josin fun.
      Leyin ti o bere ise ipepe ita gbangba, o je onisuru ti o n rankan esan lori awon oun ti o ba pade lodo awon eniyan re ninu awon orisirisi ifarani ni ilu Makkah lakoko. Leyin naa o se suru pelu awon oloju eji ti o ba pade ni ilu Madina. O je apejuwe fun suru sise nigba ti o padanu awon ololufe re, Khadijah (Olohun ki o yonu si) ti o je iyawo re papoda, bakan naa gbogbo omo re lo ku tan loju re ayafi Fatimah (Olohun ki o yonu si) nikan. Egbon baba re, Abu Talib, ati aburo baba re Hamzah (Olohun ki o yonu si) naa papoda bakan naa. O si se suru lori gbogbo awon ajalu wonyi.
      Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope; a wole pelu Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si odo baba Sayfu l yaqeen ti o je oko fun arabinrin ti o fun Ibrahim omo ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) loyan. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gbe Ibrahim o fenu ko lara, o si gboorun re, leyin naa ni a tun wole pada si odo re, bayi ni Ibrahim bere si ni pokaka iku! oju Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si bere si ni da omije, Abdur Rahaman omo A'wf si dahun wipe; ati iwo naa ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) !! Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si da lohun wipe:
:" يا ابن عوف إنها رحمة " ثم أتبعها بأخرى فقال ﷺ:"إن العين تدمع والقلب يحزن ولا نقول إلا ما يرضى ربنا وإنا بفراقك يا إبراهيم لمحزونون "
      '' ire omo A'wf, eleyi ni ike'' o tun da omije loju, o si so bayi pe '' dajudaju oju n da omije, okan si n baje, (sugbon) a ko ni so nkankan ayafi oun ti yoo yo Oluwa wa ninu, ire Ibrahim, iku re yi bawa ninu je (Al Bukhari).
32, Deede Ati ipe iwo eni
     Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je oni deede ninu gbogbo isesi isemi aye re. o je onideede nibi lilo ofin olohun. Aisha (Olohun ki o yonu si) sope '' dajudaju arabinrin Al makhzumiyah ti o jale، awon Qurayshi ni akolekan alamori oro re pupo. Won beere wipe; tani yoo ba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) soro lori re? won si dahun wipe; ko si eni ti o le se eleyi ju Usamah omo Zayd lo (Olohun ki o yonu si) ololufe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni. Usama ba Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) soro lori re, o si dahun wipe:
:" أتشفع في حد من حدود الله !! " ثم قام فاختطب ثم قال:" إنما أهلك الذين قبلكم أنهم كانوا إذا سرق فيهم الشريف تركوه وإذا سرق فيهم الضعيف أقاموا عليه الحد وأيم الله لو أن فاطمة بنت محمد سرقت لقطعت يدها"
     '' o fe ma sipe lori okan ninu awon enu aala Olohun !! leyin naa ni o dide ti o si ba awon eniyan soro bayi pe '' ninu awon oun ti o se okunfa iparun fun awon eni ti won siwaju yin ni wipe; ti eni ti o je abiyi ninu won ba jale won a fi sile, (sugbon) ti eni yepere ninu won ba jale won yoo lo ofin le lori. Mo fi Olohun bura wipe ti Fatimah omo Muhammad ba jale, ma ge owo re (Al Bukari ati Muslim).
      Sise deede re ni agbara debi wipe o ma n fi ara re sile ki won gbesan lara re. Asyad omo Khudayr (Olohun ki o yonu si) sope:
"بينما رجل من الأنصار يحدث القوم وكان فيه مزاح، بينا يضحكهم فطعنه النبي ﷺ في خاصرته بعود كان في يده، فقال: أصبرني فقال:" اصطبر " قال: إن عليك قميصاً وليس علي قميص، فرفع النبي ﷺ عن قميصه فاحتضنه وجعل يقبل كشحه وقال: إنما أردت هذا يا رسول الله.
     Nigba ti arakunrin kan ninu awon Ansar n ba awon eniyan re soro ti o si n se awada, laarin igba ti o pa won lerin, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) (seesi) fi owa ope ti o wa ni owo re gun ni egbe, o si so bayi pe '' wa gbesan oun ti mo se fun o'' o si dahun wipe; ma gbesan, sugbon aso n be lara re nigba ti ko si aso lara temi, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ka aso re soke, arakunrin yi di mo, o si bere si ni pon ikun re la, o si so bayi pe; oun ti mo fe ni mo ti se yi ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) (Abu Dawud).
33, Iberu Olohun
     Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti o beru Olohun julo ti o si paya re. Abdullah omo Masuu'd sope Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so fun mi pe:
:" اقرأ علي" قلت يا رسول الله: أقرأ عليك وعليك أنزل ! قال:" نعم " فقرأت سورة النساء حتى أتيت إلى هذه الآية: [فَكَيْفَ إِذَا جِئْنَا مِنْ كُلِّ أُمَّةٍ بِشَهِيدٍ وَجِئْنَا بِكَ عَلَى هَؤُلَاءِ شَهِيدًا ] قال: " حسبك الآن" فالتفت إليه فإذا عيناه تذرفان.
     '' ka (Al Quran) fun mi'' mo dahun wipe; bawo ni ma se ka fun o nigba ti o jepe iwo ni won so kale fun ! o sope ''beeni'' mo si ogba oro An nisa titi ti mo fi ka de ibi oro Olohun ti o sope '' bawo ni yoo se ri, nigba ti a ba mu eleri wa lori ijo kookan, ti a si mu iwo na wa ni eleri lori awon wonyi'' Q4;41, o sope '' o ti to bayi'' mo wo oju re, oju re mejeeji si n da omije (Al Bukari ati Muslim).
     Aisha (Olohun ki o yonu si) sope; ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba ri ojo ti o su ni oju sonmo, yoo ma lo yoo ma bo, yoo ma wole yoo si ma jade, oju re yoo si yi pada, sugbon ti ojo ba ro inu re yoo dun. Aisha (Olohun ki o yonu si) wa beere kin ni idi isesi yi? O si da lohun wipe:
 "ما أدري لعله كما قال قوم [فَلَمَّا رَأَوْهُ عَارِضًا مُسْتَقْبِلَ أَوْدِيَتِهِمْ قَالُوا هَذَا عَارِضٌ مُمْطِرُنَا بَلْ هُوَ مَا اسْتَعْجَلْتُمْ بِهِ رِيحٌ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمٌ] ".
     '' mi ko mo boya iru oun ti awon ijo kan so (ni o fe sele) ''nigba ti won ri (iya naa) ni esu ojo ti o bo gbangba ilu won, won sope: eyi ni esu ojo ti o ma ro fun wa. Rara, oun ti eyin kanju re ni, ategun ti iya eleta elero wa ninu re ni'' Q46:24 (Al Bukari ati Muslim).
34, Ini Itelorun Ati Ayo okan
      Umar omo Khatab (Olohun ki o yonu si) sope; mo wole to ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o sun si ori eni, ti ko si si nkankan lori eni naa. Irori ti o fi rori je eyi ti won se latara koriko ti a fi awo bo, ti awo ti won pa laro si wa nibi ese re. bakan naa ni awon awo eran ti won ko tii pa laro si wa loke ori re ti won soko sibe. Mo ri oripa eni ni egbe re, mosi bu sekun. O si beere wipe:
" ما يبكيك؟" فقلت يا رسول الله: إن كسرى وقيصر فيما هما فيه وأنت رسول الله، فقال:" أما ترضى أن تكون لهم الدنيا ولنا الآخرة".
      ''kin ni o pa o lekun ire Umar'' mo si dahun wipe; ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dajudaju Kisra ati Qaysar wa ninu ola nla (pelu aise tolohun won) iwo lo wa wa bayi ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). O wa dahun wipe '' se ko wa dun mo o ninu ki aye yi je tiwon ki orun si je tiwa'' (Al Bukari ati Muslim).
      O feran daadaa fun gbogbo eniyan lai yo awon ota re sile. Aisha (Olohun ki o yonu si) ti o je iyawo re sope; mo beere wipe:
قلت للنبي ﷺ هل أتى عليك يوم كان أشد من يوم أحد؟ قال:" لقد لقيت من قومك ما لقيت, وكان أشد ما لقيت منهم يوم العقبة, إذ عرضت نفسي على ابن عبد ياليل بن عبد كلال فلم يجبني إلى ما أردت, فانطلقت وأنا مهموم على وجهي فلم استفق إلا وأنا بقرن الثعالب, فرفعت رأسي فإذا أنا بسحابة قد أظلتني فنظرت فإذا فيها جبريل فناداني فقال: إن الله قد سمع قول قومك لك وما ردوا عليك, وقد بعث الله إليك ملك الجبال لتأمره بما شئت فيهم, فناداني ملك الجبال فسلم علي ثم قال: يا محمد فقال ذلك فيما شئت, إن شئت أن أطبق عليهم الأخشبين؟ فقال النبي ﷺ:"بل أرجو أن يخرج الله من أصلابهم من يعبد الله وحده لا يشرك به شيئا"
      ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nje ojo kan wa ti o nira lara re bi ojo (ogun) Uhud? o dahun wipe '' mo ti pade oun ti o le ni odo awon eniyan re, oun ti o lagbara julo ninu oun ti mo pade ni odo won ni ti ojo Al a'qabah, nigba ti mo lo si odo omo Abdu Yaleel omo Abdu Kilal lati dabo bomi (nibi suta Quraysh kin le ni anfani lati pepe sinu Islam) sugbon o ko lati se be. Mo gbera pelu ibanuje titi ti mo fi de ibi oke Qarnu th thaa'lib, mo gbe oju soke، ni mo ba ri pe ojiji ti bo mi, ni mo ba ri Jibreel loke, o si pe mi lo ba so pe '' dajudaju olohun ti gbo oro ti awon eniyan re n so nipa re ati bi won se ko (ipepe re), dajudaju Olohun ti gbe malaika oke yi dide pe ki o pa lase oun ti o ba wu o lori won. Ni Malaika oke naa ba pe mi, o si salamo si mi, leyin naa ni o so pe '' ire Muhammad, o sope lori gbogbo oun ti o ba fe, ti o ba fe kin si awon oke mejeeji wonyi le won lori? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa sope '' oun ti mo fe ni ki Olohun yo jade lara won awon aromodomo ti won yoo ma josin fun Olohun nikan soso ti won ko si ni se ebo pelu re'' (Al Bukari ati Muslim).
     Omo Umar (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) sope; nigba ti Abdullah omo Ubay omo Saluul (ti o je olori awon olojueji ni ilu Madina) papo da, omo re ti se Abdullah wa toro lowo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pe ki o fun oun ni aso ti won yoo fi sin baba re, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fun un. Leyin naa o tun toro lowo Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki o wa kirun si lara, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) dide lati lo kirun si lara, Umar dide o si fa aso Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), o si sope; se o fe lo kirun si lara ni leyin igba ti Olohun ti ko fun o lati kirun si lara? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe '' Olohun fun mi anfani lati se esa ni, ni o se sope
"اسْتَغْفِرْ لَهُمْ أَوْ لَا تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ إِنْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ سَبْعِينَ مَرَّةً" وسأزيد على سبعين" قال: إنه منافق, فصلى عليه رسول الله وأنزل الله عز وجل " وَلَا تُصَلِّ عَلَى أَحَدٍ مِنْهُمْ مَاتَ أَبَدًا وَلَا تَقُمْ عَلَى قَبْرِهِ". (التوبة:84)
     ''(o) toro aforijin fun won tabi o ko toro aforinjin fun won, koda ki o toro aforijin fun won ni igba aadorin'' Q9:80. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope) ''ma si se alekun lori aadorin'' Umar dahun wipe; oloju eji ma ni, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) kirun si lara, leyin naa ni Olohun wa so oro re kale pe '' o ko gbudo kirun si eyikeyi ti o ba ku ninu won mo lailai, o ko si gbudo lo si ibi saare re'' Q9:84. (Al Bukari ati Muslim).


NINU AWON EKO IBAGBEPO RE
1-    O je eni ti o sunmo awon omoleyin re ti o si  se asepo ti o yanju pelu enikookan won. Ninu awon oun ti yoo se afihan eleyi ni imo re ti o de ogongo nipa eto igbesi aye enikookan won, yala eyi ti o pamo ninu alamori ni tabi eyi ti o han si gbangba. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je awokose ni gbogbo ona patapata. Ibn Jareer omo Abdullah (Olohun ki o yonu si) sope;
 "ما حجبني النبي ﷺ منذ أسلمت, ولا رآني إلا تبسم في وجهي، ولقد شكوت إليه أني لا أثبت على الخيل فضرب بيده في صدري وقال:" اللهم ثبته واجعله هاديا مهديا"
     '' ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ko ko eyin si mi ri lati igba ti mo ti di musulumi, bakan naa ko ni ri mi ayafi ki o rerin muse si mi, mo lo so fun pe ko rorun fun mi lati joko si ori esin daada, o si fi owo re gbami laya o si se adua wipe '' ire olohun fi ese re rinle, ki o si se ni eni imona ti yoo ma fi ona mo elomiran'' (Al Bukari ati Muslim).
 O je eni ti ma nse ere ati awada pelu awon omoleyin re. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
"كان رسول الله أحسن الناس خلقا وكان لي أخ يقال له أبو عمير قال: أحسبه, قال: كان فطيماً - صغيراً - قال: فكان إذا جاء رسول الله فرآه قال:" أبا عمير ما فعل النغير - طائر - قال فكان يلعب به" (متفق عليه)
     '' ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti iwa re dara julo ninu awon eniyan. Mo ni aburo kan ti a n pe ni Abu U'mayr, o je omode ti o ti ja lenu omu, igbakugba ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba de, ti o si ri omo yi ni yoo sope '' ire baba Umayr, (eye) Nugayr nko o?'' eye ti o ma n ba sere. (Al Bukari ati Muslim).
      Ere sise ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pelu awon omoleyin re ko mo lori oro enu nikan bikosepe o tun ma n se afarase pelu won bakan naa. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope; dajudaju arakunrin ara oko kan ti won n pe ni Zahir omo Haram ma n gbe ebun wa fun ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) yoo si pese fun ni igba ti o ba fe jade. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" إن زاهراً بادينا ونحن حاضروه", قال فأتاه النبي ﷺ وهو يبيع متاعه فاحتضنه من خلفه والرجل لا يبصره, فقال أرسلني، مَن هذا ؟ فالتفت إليه فلما عرف أنه النبي ﷺ جعل يلزق ظهره بصدره. فقال رسول الله ﷺ: من يشتري هذا العبد؟ فقال زاهر تجدني يا رسول الله كاسداً, قال لكنك عند الله لست بكاسد, أو قال ﷺ بل أنت عند الله غال"
    '' e ri Zahir a n se anfani awon ere oko lati odo re, awa si je ara igboro fun un'' o sope ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lo si odo re ni asiko ti o n ta oja lowo, o si dimo lati eyin, ti ko si mo eni ti o di mo oun. O si sope; fi mi sile, iwo ta ni? o boju weyin, kete ti o mo pe ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni o le eyin re mo igbaya ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa sope '' tani yoo ra eru yi? o si dahun wipe; ire ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa ri wipe oja  ti yio kuta ni mi، o dahun wipe '' o kii se okuta lodo Olohun, tabi o sope, oja ti o lowo lori lo je lodo Olohun'' (Ibn Hiban).
      O ma nse ijiroro pelu awon omoleyin re ti o si ma n gba imoran lodo won lori awon oro ti alaye re ko ba si ninu Al Quran. Abu Hurayra sope:
"مارأيت أحداً أكثر مشورة لأصحابه من رسول الله ﷺ ".
     '' mi o mo enikan ti o ma n se imoran pelu awon omoleyin re ti o to ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba)'' (At tirmidhi).

2-     Imo Se Abewo Awon Alaisan (Musulumi Tabi Eni Ti Ki Se Musulumi).
      O ma n beere nipa awon omoleyin re, o si ma se iwadi nipa won. Ti o ba gbo iro pe enikan nse aisan ninu won, yoo gbera  oun ati awon ti o ba wa pelu re ni asiko naa lati se abewo onitohun. Abewo re ko mo lori awon ti o je musulumi nikan soso bikosepe o tun ma n be awon ti ki se musulumi naa wo. Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
 "كان غلام يهودي يخدم النبي ﷺ فمرض، فأتاه النبي ﷺ يعوده، فقعد عند رأسه، فقال له: " أسلم "، فنظر إلى أبيه وهو عنده، فقال له: أطع أبا القاسم ﷺ ، فأسلم، فخرج النبي ﷺ وهو يقول: " الحمد لله الذي أنقذه من النار "
'' odomode yehuudi kan ti ma n ran ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lowo nse aisan, ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si lo se abewo re, o joko si ibi igberi re, o si so fun pe '' gba esin Islam'', omo yi wo oju baba re ti o joko ti, baba re si so fun pe: se oun ti baba Qasim ni ki o se' omo yi ba gba Islam, ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si jade ni eni ti nso pe '' ope ni fun Olohun ti o laa kuro nibi ina'' (Al Bukhari).

3-    Ima Dupe Oore Ati Fifi Daadaa San Daadaa
     O so ninu oro re pe:
: " من استعاذكم بالله فأعيذوه ، ومن سألكم بالله فأعطوه، ومن دعاكم فأجيبوه، ومن صنع إليكم معروفاً فكافئوه، فإن لم تجدوا ما تكافئونه فادعوا له حتى تعلموا أن قد كافأتموه "
     '' eni ti o ba sa si odo yin fun idabobo nitori Olohun, e daabo boo. Eni ti o ba toro lowo yin nitori Olohun, e fun un. Eni ti o ba pe yin, e da lohun. Eni ti o ba se daadaa si yin, e san pada fun, ti e ko ba wa ri oun ti e o fi san pada, e se adua fun titi ti e o fi ni amodaju wipe e ti san pada fun'' (Abu Dawud). Aisha (Olohun ki o yonu si) sope:
"كان رسول الله ﷺ يقبل الهدية ويثيب عليها".
     '' ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eni ti o ma ngba ebun ti o si ma san esan dipo re'' (Al Bukhari).

4-    Fiferan Oun Ti o Dara Ati Lofinda Ti o ni Oorun Didun
 Anas omo Malik (Olohun ki o yonu si) sope:
 "ما مسست حريرا ولا ديباجا (نوع من الثياب المصنوعة من الحرير الخالص) ألين من كف النبي ولا شممت ريحا قط أو عرفا (ريحا) قط أطيب من ريح أو عرف النبي".(متفق عليه)
      '' mi o fowo kan aso aran (ariiri) tabi aso siliki kan ri ti o wa fele bi owo ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), bakan naa mi o si ri lofinda tabi turari ti o wa ni oorun didun ti o da bi ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). (Al Bukari ati Muslim).

5-    Inife Mimo Sipe Fun ni nibi Gbogbo Daadaa.
      Omo Abas (Olohun ki o yonu si awon mejeeji) sope: oko Bareera ti won npe ni Mugeeth je eru, o dabi wipe mo nwo ti o nsare leyin Bareera tekun tekun, ti omije si nsan ni parike re. ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa so fun Abas wipe
"يا عبَّاسُ ألا تعجَبُ من حبِّ مغيثٍ بريرةَ ومن بُغضِ بريرةَ مُغيثًا" فقالَ لها النَّبيُّ صلَّى اللَّهُ عليهِ وسلَّم: "َ لو راجعتيهِ فإنَّهُ أبو ولَدِكِ" قالت "يا رسولَ اللَّهِ تأمُرُني؟" قالَ "إنَّما أشفَعُ" قالت "لا حاجةَ لي فيهِ".
     '' ire Abas se ko wa se o leenmo ni, bi Mugeeth se feran Bareera to, ti Bareera si korira re!! ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wa so fun Bareera pe '' ti o ba si da oro re ro, oun ma ni baba omo re'' o wa dahun wipe: ire ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se o n pa mi lase ni? o si dahun wipe '' mo n sipe fun ni'' Bareera si dahun pada pe '' mi o ni nkankan se pelu re mo'' (Ibn Majah).

6-    Ima Se Ise Re Fun Ra Re
      Aisha (Olohun ki o yonu si) dahun, nigba ti won bi leere wipe kin ni oun ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ma nse ninu ile re?
"كان بشراً من البشر، يفلي ثوبه (ينظفه من القمل)، ويحلب شاته، ويخدم نفسه". (صحيح ابن حبان)
     '' eniyan ni oun naa gegebi ti awon yoku, o ma nfo egbin kuro nibi aso re, o si ma nfun wara eran, o si ma se ise re funra re'' (Ibn Hiban).
     Koda, iwa alaponle ti nbe ni ara re ma nje ki o se ise fun elomiran yato si ara re. Aisha so nipa re, nigba ti won bi leere nipa oun ti o ma nse ninu ile? O sope:
"كان يكون في مهنة أهله (الصنعة، والمراد شغل أهله وحوائجهم). فإذا سمع الأذان خرج ".
     '' o ma be nibi sise ise fun awon ara ile re, nigba ti o ba si gbo ipe irun yoo jade''. (Al Bukhari).

 

AWON IJERI DEEDE
      Gbajumo olukowe omo orilede Germany, Geothe sope: mo se iwadi ijinle nipa itan omoniyan lati mo tani o je awokose ti o ga julo, mo si ri pe Anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o je larubawa ni, (Muhammad, ninu awon eko ijinle mimo).
      Ojogbon (prof.) Keith Moore so ninu iwe re " bi omoniyan ti n dagba soke'' wipe: ko ni mi lara lati gba pe dajudaju Al Quran oro Olohun ni. Toripe alaye nipa ole inu (oyun) ti o wa ninu re ko rorun lati mo ni iru ogorun odun keje. Ona kan soso ti o ba lakaye mu naa ni ki a mo pe awon alaye wonyi sokale lati odo Olohun fun Muhammad ni.
      Will Durant so ninu iwe re '' itan olaju, idi kokanla (vol. 11) '' wipe: ti a ba fe so ododo nipa ije eniyan nla, eni ti o lapa lara awon eniyan, a o sope: dajudaju ojise awon musulumini eni ti o pataki julo ninu awon eniyan pataki ninu itan omoniyan. O wu gbongbo eleyameya ati awon isesi ti ko wulo kuro lawujo. O fi esin ti o rorun pupo, ti ko ni iruju ninu, ti o ni ipile, ti o si lagbara bori esin Yehuudi, kirisiteni ati esin awon eniyan re ti o ba ni ilu Makkah. Esin naa si nbe titi di asiko yi pelu agbara ti o bani leru.
      George de Borns so ninu iwe re '' ile aye'' wipe: dajudaju, ima se iyemeji nipa gbigbe dide ni ojise Muhammad je iseyemeji nipa agbara Olohun ti o ko gbogbo agbanla aye sinu patapata.
      Ojogbon Wale n so ninu iwe re '' Anabi Ododo'': eyi to lagbara julo ninu awon eri ti o n toka lori ije olododo ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), ni jije  akoko awon ara ile ati awon alasunmo re ninu awon eni ti o gbaa gbo. won mo gbogbo koko ati gbangba re patapata. Ti won ba se iyemeji nipa ije olododo re ni, won ko ba ti gbagbo.
      Olukeko esin Islam ti ki se musulumi, Hill so ninu iwe re '' olaju awon larubawa'' wipe: a ko mo esin kan ninu itan omoniyan ti o yara tanka ti osi yi eto igbesi aye omoniyan pada gegebi ti esin Islam! Muhammad so ijo tuntun di mimo fun gbogbo agbaye, o si fi ijosin fun Olohun lele  lori ile. O fi ipile deedee ati dogban dogba lele laarin awujo, o si fi ilana, eto, ofin, itele ase ati iyi lele fun awon eniyan ti won ko mo ju rogbodiyan lo tele.
      Jean Luc, olukeko esin Islam ti ki se musulumi, ti o je omo orile ede Spain so ninu iwe re '' Iran Larubawa'' wipe: igbesi aye Muhammad ko se royin dara ju bi Olohun se royin re ninu Al Quran lo wipe:
 " وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلاَّ رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ " ( الأنبياء 107 )
     '' a ko ran o bikose lati je ike fun gbogbo agbaye '' Q21: 107.
     Ni ododo Muhammad je ike otito. Mo si ma ntoro ike fun pelu ibanuje (pe mi o ri) ati ife.
      George Bernard Shaw so ninu iwe re '' Esin Islam Leyin Ogorun Odun'' wipe: dajudaju gbogbo aye patapata ni yoo gba fun esin Islam, enii ti ko ba gba ni oruko ti o foju han yoo si gba pelu ayipada oruko. Ojo naa nbo ti awon oyinbo (West) yoo ma gba esin Islam. Awon asiko ti awon oyinbo (West) nka awon iwe iro nipa esin Islam ti bo seyin. Mo ti ko iwe kan nipa Muhammad, bi o tile jepe ede ati ilana oyinbo ni mo fi ko.


AWON IYAWO RE
     Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fe iyawo ti o le ni mewa leyin iku Khadija ti o je iyawo re alakoko. Gbogbo won patapata  agbalagba (adelebo) ni won ayafi Aisha nikan ni o fe ni olomoge (Olohun ki o yonu si gbogbo won). Mefa ninu won ni won je iran Qurayshi ti okan si je yehuudi nigba ti awon yoku si wa lati inu awon iran larubawa miran. Okan ninu won nje Mariyatu l Qibtiyah, ti Al Maqawqis, oba Alexandria fi ta lore, oun si ni mama Ibrahim (Olohun ki o yonu si won). Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
: " إنكم ستفتحون مصر وهي أرض يسمى فيها القيراط, فإذا فتحتموها فأحسنوا إلى أهلها فإن لهم ذمة ورحما, أو قال ذمة وصهرا "
      '' dajudaju e o si ile Misira (Egypt). Oun ni ile ti won npe ni Al Qeerat, ti e ba ti si tan e se daadaa si awon ara ibe, toripe iwo ati ibanitan nbe fun won, tabi o sope '' iwo pelu eto ati ijeana'' (Muslim).
وقال ﷺ أيضاً: " إذا ملكتم القبط (هُم أهل مِصر) فأحسنوا إليهم فإن لهم ذمة ورحما "
      O tun sope '' ti e ba ile Misira jogun, e se daadaa si won toripe won ni iwo pelu eto ati ibatan (Musanaf Abdur Razaq).
     O fe iyawo ti onka re po to bayi nitori awon idi orisirisi:
1-    Lati Fi Ofin Esin Lele Fun Awon Eniyan.
 Gegebi o se fe Zaynab omo Jahsh (Olohun ki o yonu si). Toripe ni aye igba naa o je eewo laarin awon larubawa ki eniyan fe iyawo omo ti o gba to ti o si ti so di omo re. Toripe won gba wipe iyawo omo ti a gba to da gegebi iyawo omo eni ni. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fe Zaynab lati yi  irori yi pada. Olohun sope:
فَلَمَّا قَضَى زَيْدٌ مِنْهَا وَطَرًا زَوَّجْنَاكَهَا لِكَيْ لَا يَكُونَ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ حَرَجٌ فِي أَزْوَاجِ أَدْعِيَائِهِمْ إِذَا قَضَوْا مِنْهُنَّ وَطَرًا وَكَانَ أَمْرُ اللَّهِ مَفْعُولًا
     "ni igbati zayd gbo bukata re tan lara re  ase ni iyawo fun o ، nitori ki o mo je waala fun awon olugbagbo ododo lati fe awon  iyawo omo ti won gba to leyin ti won ti gbo bukata won lara won ،  ase olohun oun ti ati pari ni" '' Q33:37.
2-    Nitori Oselu (Esin)
      Fun anfani ipepe esin ati lati fa okan awon idile kookan mora ati lati ri itutu oju won. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) di ana pelu molebi ti o tobi julo ninu Qurayshi, ti o si je eyi ti o lagbara julo ninu iran larubawa. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ko fi mo lori ara re nikan koda o tun pa awon omoleyin re lase ki won se be. O so fun Abdur Rahaman omo Awf nigba ti o ran lo si Dawmatu l Jundul wipe:
 " إن أطاعوك فتزوج ابنة ملكهم "
     '' ti won ba gba fun o, fe omo oba won'' (Tareekhu At tabri 2\126)
      Cl. Cahan sope '' o seese ki a korira awon apakan ninu ilana isemi aye re, latara ilana ironu wa ti o je ti igbalode. Orisirisi igbese ni o ti fi idi re mule wipe ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je onifekufe emi! pelu itokasi lori awon iyawo mesan ti o fe leyin iku Khadijah (Olohun ki o yonu si). Sugbon eyi ti o fese rinle ti o si je ododo ni wipe pupo ninu awon iyawo wonyi ni o fe nitori oselu (esin). O fewon lati ni asepo pelu awon eniyan nla ati awon ti o pataki ni awujo. Bakan naa ni wipe iran larubawa kii tako oun ti o ba adamo omoniyan mu nigba ti o ba lo ni ona ti o ye''
3-    Fun Amojuto Awujo
      Apere eleyi ni iyawo awon omoleyin re ti o fe leyin ti won ku si oju ogun esin. O fewon pelu wipe won ti di agbalagba, lati mojuto awon alamori won ati lati fi se aponle fun awon ati awon oko won.
      Arabinrin L. Veccia Valglieri ti o je omo orile ede Italy so ninu iwe re " Idaabobo Esin Islam'' wipe: dajudaju Muhammad je enikan ti o jepe ni asiko odo re, ti agbara ibalopo pelu obinrin wa ni pipe, ti o si nsemi laarin awujo ile larubawa ti igbeyawo je oun ti ko pataki lawujo, ti o si je pe ki eniyan ni iyawo pupo je oun ti o gbajumo laarin won, bakan naa ti ikora eni sile si je oun ti o rorun pupo, pelu gbogbo eleyi ko fe ju iyawo kan lo ti se Khadija (Olohun ki o yonu si), ti arabinrin naa si ju lo pupo ni ojo ori.
      Laarin odun meedogbon ti won fi se loko laya ko fe obinrin miran pelu re ayafi leyin igba ti o pa ipo da, eleyi leyin igba ti o pe omo aadota odun.
      Ikookan ninu awon iyawo ti o pada fe ni o fewon nitori eto imojuto awujo tabi nitori oselu (esin). Toripe ikookan ti o fe ninu won ni o jepe o gbero lati se aponle fun awon ti o beru Olohun ninu won, tabi lati fi se asepo pelu awon iran tabi molebi miran fun anfani titanka esin Islam. Muhammad ko fe enikankan ti o je omoge, odo tabi arewa ayafi Aisha (Olohun ki o yonu si) nikan. Nje se o ye ki a pe iru eniyan bayi ni onisekuse tabi onifekufe emi bi? Eniyan ni oun naa kii se Olohun. O le jepe nitori omo ni o fi fe iyawo miran…… pelu wipe ko ni ona ola repete, o gba lati la bukata molabi nla borun. O je oni deedee pelu gbogbo won, ko si se igbese lati ko eyikeyi sile ninu won.
 Eyi ti o se yi nbe ni ibamu si isesi awon Anabi Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba gbogbo won) ti o siwaju re, gegebi Anabi Musa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ati awon miran ninu awon ti awon eniyan ko so aburu nipa bi won se fe awon iyawo ti o po. Nje idi eleyi ni wipe a ko mo nipa isemi aye won, ti o fi wa je pe Muhammad nikan ni a n soro nipa molebi re?
 Thomas Carlyle naa so ninu iwe re ti o gbajumo " Awon Akoni " wipe: Muhammad ki se onifekufe emi rara, gbogbo esun ti won fi kan ni abala yi je ti abosi ati ote. Olori abosi ati asise ni ki a pe ni onifekufe emi ti ko si oun ti o kan ju ki o ba obinrin lopo lo. Ti o si jepe o je eni ti o jina si eyikeyi igbadun ni gbogbo ona.


DIE NINU AWON ERI TI O N TOKA LORI WIPE ANABI ATI OJISE OLOHUN LO JE
 (IKE ATI OLA OLOHUN KI O MA BA)

AWON ERI LATI INU AL QURAN
     Olohun ti ola re ga so bayi pe:
[مَا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَا أَحَدٍ مِنْ رِجَالِكُمْ وَلَكِنْ رَسُولَ اللَّهِ وَخَاتَمَ النَّبِيِّينَ] (الأحزاب 40)
     '' Muhammad ki se baba enikankan ninu yin bikose ojise Olohun ati igbeyin awon Anabi'' Q33:41.
       Anabi Issa ti so asotele nipa anabi Muhammad ninu Injeel.         Olohun so bayi pe:
وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِنْ بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ
     '' nigba ti Issa omo Maryam sope: eyin omo Israeel, ojise Olohun ni mo je siyin, ti mo nse afirinle oun ti nbe lowo mi ti se At tawrah, ti mo si nfun yin niro nipa ojise ti n bo leyin mi ti oruko nje Ahmad '' Q61:6.
      Olohun tun so bayi pe:
 الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ الرَّسُولَ النَّبِيَّ الْأُمِّيَّ الَّذِي يَجِدُونَهُ مَكْتُوبًا عِنْدَهُمْ فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنْجِيلِ يَأْمُرُهُمْ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَاهُمْ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُحِلُّ لَهُمُ الطَّيِّبَاتِ وَيُحَرِّمُ عَلَيْهِمُ الْخَبَائِثَ وَيَضَعُ عَنْهُمْ إِصْرَهُمْ وَالْأَغْلَالَ الَّتِي كَانَتْ عَلَيْهِمْ فَالَّذِينَ آمَنُوا بِهِ وَعَزَّرُوهُ وَنَصَرُوهُ وَاتَّبَعُوا النُّورَ الَّذِي أُنْزِلَ مَعَهُ أُولَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ (157)
"      awon  ti won ntele ojise anobi ti o le ko ti o le ka، eni ti a da oruko re ninu taorat ati injeel، ti n pawonlase dada، ti nko aburu fun won، ti n se gbogbo nto dara leto fun won، ti n se gbogbo nto je egbin leewo lori won، tin mu kuro fun won awon eru ese ati ajaga asise، eni to ba gbaagbo tosi bowo re tosi ran lowo to tele imole re eyi ti a sokale fun، awon ni olujere"
Q7: 157

ERI LATI INU ORO RE (SUNNAH)
     Oro re ti o sope:
" إن مثلي ومثل الأنبياء من قبلي كمثل رجل بنى بيتا فأحسنه وأجمله إلا موضع لبنة (حجر) من زاوية فجعل الناس يطوفون به ويعجبون له ويقولون: هلا وضعت هذه اللبنة؟ قال: فأنا اللبنة وأنا خاتم النبيين"
     '' apejuwe ati awon Anabi ti o ti wa siwaju mi da gege bi apejuwe arakunrin kan ti o mo ile kan ti o si mo ile naa daradara ti o si se ni oso sugbon ti aaye biriki kan sile ni igun ile naa, awon eniyan nrokirika ile naa won si n se enmo (lori bi ile naa se dara to) ti won si nso pe: kilode ti ko wa gbe biriki kan ti o ku si? ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope '' emi ni biriki naa emi ni igbeyin awon Anabi'' (Al Bukari ati Muslim).

 ERI LATI INU AWON TIRA TI O SIWAJU LATI ODO OLOHUN
LATI INU TAORETA (MOJEMU LAILAI)

     A'tau omo Yassar (Olohun ki o yonu si) sope: mo pade Abdullah omo A'mru omo Al Aa's (Olohun ki o yonu si awon mejeeji), mo wa so fun pe: fun mi ni iro nipa iroyin ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lati inu iwe Taoreta? O si dahun wipe:
"أجل والله إنه لموصوف في التوراة ببعض صفته في الفرقان "يا أيها النبي إنا أرسلناك شاهدا ومبشرا ونذيرا وحرزا للأميين, أنت عبدي ورسولي, سميتك المتوكل ليس بفظ ولا غليظ ولا صخاب بالأسواق, ولا يدفع السيئة بالسيئة ولكن يعفو ويغفر, ولن أقبضه حتى أقيم به الملة العوجاء, وأن يقولوا لا إله إلا الله, وأفتح به أعيناً عمياً وآذاناً صماً وقلوباً غلفاً "

     " beeni, mo fi Olohun bura wipe iroyin re nbe ninu Taoreta gege bi  o se wa ninu Al Furqan (Al Quran) '' ire Anabi dajudaju a ran o lati je eleri ati olu fun ni ni iro idunnu ati lati je olukilo ati lati je idaabobo fun awon ti o mo ko ti ko mo ka, eru ati ojise mi ni o je, mo so e ni olugbarale mi ti ki se alagidi ti ko dara ni iwa, oninu fufu tabi eniti o ma n pariwo ni aarin oja, kii fi aburu san aburu biko sepe o ma nse aforijin ati amoju kuro. Mi o ni gba emi re titi ti ma fi fi se atunse oju ona (esin) ti o ti daru, titi won yoo fi so wipe ko si eni ti o leto si ijosin ayafi Olohun, ma fi la awon oju ti o ti fo ati awon eti ti oti di ati awon okan ti o ti tipa '' (Al Bukhari).
      Ojogbon onimimo (prof.) Abdul Ahad ti o je elesin Yehuudi so bayi pe ''………. Sugbon mo gbiyanju lati gbarale awon apakan ninu awon Bibeli Mimo ninu iwadi mi. Toripe o kere ninu igba ti iyan jija le waye lori re ni abala ede. Mi o lo si inu ede Latin, Greek tabi Aramic, toripe won ko le fun mi ni oun ti a fe fayo jade. Sugbon ma se akojo ninu awon igbese ti nbo awon oro lati inu Bibeli Mimo ni deedee bi o se wa ninu atejade ti igbimo fun Bibeli Mimo ti ilu Britain ati ti ajoji.
      E je ki a ka awon gbolohun wonyi ti o wa ninu akosile iwe Diutaronomi ninu Taoreta (ori kejidinlogun ese kejidinlogun): '' Emi yoo gbe anabi kan dide fun wo laarin awon arakunrin won, ti yoo da bi ire, emi o fi oro mi si ni enu'' (Diutaronomi 18:18).
     Ti o ba je pe oro yi ko da lori Muhammad, a je wipe ko si imuse fun oro naa. Anabi Issa (Jesu) (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ko pe apemora pe oun ni oro yi ntoka si, ti o fi je wipe awon omoleyin re naa mo wipe kii se anabi Issa (Jesu) (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni oro naa da le lori. Koda won wa ninu ireti pe ki jesu tun pada wa leekan si ki oro anabi naa le di imuse. Titi ti o fi di asiko yi ni oro yi nbe lai ni iyipada.
    Toripe wiwa ti akoko ti o je ti Jesu, ko si oun ti o toka ninu oro yi wipe oun ni eni ti oro naa ntoka si '' ma gbe anabi kan dide fun won ti yoo da bi ire''. Bakan naa ko toka lori pipada wa anabi Issa (Jesu) (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni eekeji. Toripe ni ibamu si igbagbo awon elesin kirisiteni Jesu yoo farahan gegebi adajo ni, ko ni wa gegebi eni ti o mu ofin tuntun wa. Nigba ti eni ti won se adehun re yoo wa ni eni ti yoo gbe ofin dani gegebi ina tin tan ni owo otun re''.
      Nigba ti a se iwadi nipa wipe tani anabi naa ti nbo, a ri wipe oun naa ni anabi ti won se afiti re si odo anabi Musa (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Bawo ni yoo se wa? Ibeere yi yoo ranwa lowo pupo nigba ti a ba nsoro nipa '' imole Olohun ti ntan ti yoo wa lati (oke) Faaran'' eleyi si ni oke Makkah. Bakan naa awon gbolohun ti o waye ninu iwe Diutaronomi ori ketalelogbon ese keji bayi pe '' Oluwa de lati oke Sinai o si yo si won lati Seiri, o n tan imole bo lati oke Faarani, awon enimimo egberun mewa (10,000) si de pelu re, lati owo otun re ni  awon ofin kan  ti jade fun won wa'' Diutaronomi 33:2.
      Ninu awon gbolohun o se afijo imole oluwa pelu imole Oorun '' o de lati oke Sinai, o si yo si won lati Seiri '' ''ti o si n tan imole bo lati oke Faaran'' '' awon enimimo egberun mewa si de pelu re'' '' o si gbe ofin amu bina dani fun won ni owo otun re''. ko si enikankan ninu awon omo Israeel titi ti o fi de ori anabi Issa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o ni ibatan pelu ''Faaran'' bi ko sepe Hajara ati omo re Ismaeel ni won jo lo ti won nbo lori ile Biru Saba' ( odo saba) awon ni won si gbe ilu Faaran.
     Iwe Jenesisi orikokanlelogun ese kokanlelogun sope '' o si joko si ilu Faaran, iya re si fe iyawo fun un lati ile Egipti wa'' omo re akoko si ni Qedari "Adnan'' awon aromodomo ti won nje Larubawa ni won tedo si oke Faaran lati igba naa, ti won si so ibe di ibugbe won".
     Ti o ba jepe Muhammad, - gege bi oun ti o gbajumo laarin awon eniyan - je aromodomo Ismaeel ati omo re Qedari (Adnan), ti anabi kan si jade lati oke Faaran, ti o si wo Makkah pelu awon enimimo egberun mewa, ti o si mu ofin amubina dani fun awon eniyan re. se ki wa se eleyi ni anabi ti oro re ti siwaju bi, ti o si wa si imuse gege bi o se wa ni akosile?
      Leyin eleyi, iwo ije anabi ti o muwa ni bukata si iwoyesi ati akiyesi: '' enimimo lati oke Faaran, ti titobi re kari gbogbo oke orun ati ile, awon mejeeji si kun fun eyin ati afomo re''. gbolohun ''eyin'' ni agbegbe yi ni itumo ti o kun fofo, toripe itumo oruko Muhammad naa ni "eni eyin'', eyi ti o tun pataki julo ni wipe awon iran larubawa ti won ngbe ni oke Faaran je eni ti won se adehun fun pe imisi yoo sokale fun won. ''  ki aginju ati ilu nla gbe ohun won soke,  awon ile ti Qedari (Adnan) ngbe, je ki awon ti ngbe apata korin, je ki won ho lati ori oke wa, je ki won fi ogo fun Oluwa, ki won si wi iyin re ni erekusu. Oluwa yoo jade bi okunrin alagbara, yoo ru owu soke bi ologun, yoo kigbe, nitooto yoo ke ramuramu, yoo bori awon ota re'' Aisaya 42: 11-13.
      Awon aaye meji miran ti o tun gba akiyesi lori oro ije anabi re ni itoka ti o waye lori Qedari (Adnan) ni ori ogota ninu iwe Aisaya wipe '' dide, tan imole, nitori imole re de, ogo Oluwa si yo ni ara re,…… opolopo rakunmi yoo yipo re, ti won o de pelu nkan alumoni ile ati owo oya ati awon nkan ini to po, gbogbo won yoo wa lati ile sheyba, won o mu wura ati turari wa, won yoo fi iyin Oluwa han sode. Gbogbo awon eran Qedari yoo kora jo si odo re, awon agbo Nebaioti yoo se iranse fun o, won yoo goke wa si pepe mi pelu itewogba, emi o si se ile ogo mi ni ogo. (Aisaya 60:1&6-7).

      Bakan naa, oro nipa ije anabi re miran tun waye ninu iwe Aisaya ori kokanlelogun ese ketala titi de iketadinlogun bayi pe: ''oro imisi lati ile larubawa, ninu ogun ile larubawa ni eyin yoo wo, eyin egbe ero Dedanimu. Eyin olugbe ile Tema bu omi wa fun eni ti ongbe ngbe, gbe onje won wa  fun eni ti nsalo. Nitori won nsa fun ida, fifayo, ati fun orun kikan ati fun ibanuje ogun. Nitori bayi ni oluwa ti so fun mi, ki odun kan to pe, gege bi odun alagbase, gbogbo ogo Qedari yoo wo. Iyoku ninu iye awon tafatafa, awon alagbara ninu awon omo Qedari yoo dinku'' (Aisaya 21:13-17).
      Ka awon oro ije anabi re wonyi ninu iwe Aisaya gege bi o se wa ninu awon apakan iwe Taoreta eyi ti nso nipa 'dide imole olohun lati ile Faaran'. Nigba ti o jepe Ismaeel lo tedo si oke Faaran ti o si bi Qedari (Adnan) sibe ti o si jepe oun ni baba nla awon iran larubawa, ti o si tun jepe adehun ti siwaju fun awon omo Qedari (Adnan) wipe imisi Olohun yoo sokale fun won, ti o si wa jepe oranyan ni lori awon  (iran) Qaderi ki won tewogba enimimo yi ni aponle fun ile abiyi, ile nla nigba ti okunkun ti gba ori ile fun aimoye ogorun odun. Leyin naa ni imole Olohun wa tan ni agbegbe ile yi. Ti o ba jepe gbogbo aponle wonyi ti o sele si Qedari ninu onka repete awon tafatafa ati awon akin alaponle ninu aromodomo Qedari. Ti o si jepe gbogbo awon aponle wonyi yoo pare laarin odun kan soso, leyin ti won ti sa fun awon ida amu bere bere, ati awon orun kikan.
       Nje awon oro wonyi wa se deedee enikankan lati ile Faaran ju Muhammad lo bi? '' Olohun yoo ti Temani wa, ati eni mimo lati oke Faaran. Ogo re bo awon orun, ile aye si kun fun eyin re'' (Habakuku 3:3).
     Muhammad je aromodomo Ismaeel ti o je baba Qedari (Adnan) ti o tedo si oke Faaran. Muhammad si ni anabi kan soso ti iran larubawa ri imisi Olohun lati ipase re, nigba ti okunkun ti bo gbogbo ori ile. Latara re ni imole Olohun fi tan ni ile Faaran. Ilu makkah nikan ni gbogbo agbaye ni won si ti nse eyin fun oruko Olohun ni ile Re. (bayi ni awon (iran) Qedari gba imisi Olohun laaye nile Olohun)
      Muhammad je eni ti awon ijo re fi inira kan an ti o si fi iponju jade kuro ninu ilu Makkah, ongbe gbe ni eni ti nsalo fun awon ida ti o mu bere bere ati awon orun kikan, sugbon leyin odun kan ti o jade ni ilu Makkah, awon aromodomo Qedari (ara ilu Makkah) lo kogun ba ni Badr, aaye yi ni akoko ibi ti ogun ti waye laarin awon ara Makkah ati Anabi Muhammad (ike eti ola Olohun ki o ma ba). Bayi ni o se ja awon aromodomo Qedari logun, ti gbogbo awon ogo won si pare. Ti o ba jepe gbogbo awon anabi ti won siwaju ko si eni ti o gba imisi Olohun yi ninu won, ti awon asotele wonyi ko si se lewon lori (ti ko si tun se lori anabi Muhammad), itumo re ni wipe awon asotele wonyi ko ti wa si imuse?
      Bakan naa, dajudaju " ile Oluwa ti won ti nyin oruko Re '' ti won ntoka si ninu iwe Aisaya ori ogota ese keje '' ………..won yoo goke wa si pepe mi pelu itewogba, emi o si se ile ogo mi ni ogo '' (Aisaya 60:7), oun naa ni ile Olohun alaponle ti o wa ni ilu Makkah, kii se ile ijosin awon kirisiteni (soosi) rara gege bi igbagbo awon olusalaye esin awon elesin kirisiteni. Nitoripe gbolohun ''  (iran) Qedari '' gege bi o se wa ninu ese keje, ko ni asepo Kankan pelu ile ijosin (soosi) awon elesin kirisiteni rara.
      Eyi ti o je ododo ni wipe ilu Qedari ati awon olugbe inu ilu naa ni awon iran kan soso ni gbogbo agbaye ni asiko naa ti won ko ni imo kankan nipa oun ti nje ilana ati esin kirisiteni. Bakan naa onka egberun mewa awon enimimo ti o waye ninu iwe Diutaronomi je eyi ti o ni itumo ti o kun rere '' Olohun tan imole re jade lati oke Faaran wa, awon egberun mewa enimimo si wa pelu re'' Diutaronomi 33:2.  
     Ti o ba ka gbogbo awon iwe itan ti o soro nipa oke Faaran patapata, oo ri wipe ko si ikankan ninu won ti o so isele ti o yato si awon oun ti a so soke wonyi.
 Ni igba ti Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gba ilu Makkah pada, o wo ilu naa pelu egberun mewa awon onigbagbo ododo ninu awon omoleyin re lati ilu Madina. O si gba ile Olohun lo ni eni ti o mu ofin dani, ti o si pa gbogbo awon ilana ati ofin ti o siwaju re re. Dajudaju emi otito (olutunu) eyi ti anabi Issa (Jesu) (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so asotele nipa re kii se elomiran ju Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lo, ko si ye ki a so pe oun ni emimimo ni iwoye tiwa yato si oro awon ijo Al lahuti. Anabi Issa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope '' sugbon otito ni emi nso fun yin; anfani ni yoo je fun yin bi emi ba lo: nitori bi emi ko ba lo, Olutunu ki yoo to yin wa; sugbon bi mo ba lo emi yoo ran si yin'' Johanu 16: 7, itumo awon gbolohun wonyi lai ni iruju ninu ni wipe, o je dandan ki Olutunu naa wa leyin anabi Issa (ike ati ola Olohun ki o ma ba), bakan naa ni wipe ko si pelu re ni asiko ti nsoro yi. Nje o ye ki a so pe anabi Issa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) nbe lai ni emi mimo (ti a ba gba pe olutunu naa ni emi mimo), nitoripe wiwa saye emi mimo yoo sele pelu mojemu ki anabi Issa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) kuro laye?
      Bakan naa, ona ti Jesu (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gba royin re je ki a mo pe eniyan ni Olutunu naa kii se emi mimo '' nitori ki yoo so ti ara re, sugbon ohunkohun ti o ba gbo oun ni yoo ma so'' Johanu 16:13, nje o wa ye ki a so pe Olohun ati emi mimo wa lotooto bi '' atipe emimimo ma  soro ti ara re ati oun ti o ba gbo lati odo Olohun''? Dajudaju awon gbolohun anabi Issa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ntoka lori wipe enikan ti Olohun yoo ran ni o npe ni Emi otito (Olutunu). Al Kurani paapaa naa so deedee iroyin yi nipa anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba)
[ بَلْ جَاءَ بِالْحَقِّ وَصَدَّقَ الْمُرْسَلِينَ]
'' Beeko, o mu ododo wa, atipe o jeri awon iranse (ti o siwaju) Q37:37.

LATI INU INJILA
Awon eri orisirisi lo wa ninu tira Injila ti nso nipa dide ati ije anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ati awon apakan ise ti yoo se ni ona ti ko ni iruju ninu rara.
 Iwe Johanu ori kinni lati ese ogun titi de medogbon (Johanu 1:20-25)
20- o si jewo, ko si se, o si jewo pe, Emi ki se Krisiti naa,
21- won si bi wipe, tani iwo se? Elijah ni o bi? O si wipe beeko. Iwo ni anabi naa bi? O si dahun wipe beeko.
22- Nitori won wi fun un pe tani iwo se? ki awa ki a le fi esi fun awon ti o ran wa. Kini o wi nipa ara re?
23- o wipe, emi ni ohun eni ti nkigbe ni aginju, e se  ona Oluwa ki o to, gege bi woli Isaiah ti wi.
24- awon ti a ran si je ninu awon Farisi.
25- won si bi leere, won wi fun pe, nje ese ti iwo fi nse aribomi, bi iwo ki iba se Krisiti naa, tabi Elijah, tabi Anabi naa?
Anabi ti won nsoro re nibi yi ki se anabi Isa (ike ati ola Olohun ki o ma ba), bikose pe Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni, toripe Johanu ma npepe o si tun ma nse aribomi, toun ti be naa o si tun ma salaye nipa dide anabi naa.
Johanu 14:16 '' Emi yoo beere lowo Baba, oun yoo si fun yin ni Olutunu miran, ki o le ma ba yin gbe titi lailai ''
 Gbolohun ''Oluranlowo'' ti o waye ninu Injila ni o tun tumo si ''Olutunu'' ti o si tun tumo si '' Ahmad '' eleyi si ni gbolohun ti o wa ninu Al Kurani ninu suratu Soff  
'' atipe (se iranti) nigbati Isa omo Mariyama sope: eyin omo Israila, dajudaju emi je ojise Olohun si yin ti o njeri ododo si ohun ti o ti siwaju ninu Taoreta mi si je olufun (yin) niro idunnu nipa ojise kan ti yoo de leyin mi, ti oruko re yoo si ma je Ahmad '' Q61:6.) ti o si je oruko miran fun Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba).
      Bakan naa, o wa ninu Injila Barnaba, ori ogofa din mejo ese kokanlelogota titi de ogorin (112:61-80) wipe anabi Isa (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope '' nitoripe Olohun yoo gbe mi kuro ni ori ile, yoo si pa oju onijamba da (si temi), ti gbogbo eniyan yoo si ro pe oun ni emi, pelu bayi ni yoo ku iku inira, emi yoo si wa pelu iroyin iyepere yi fun igba pipe, titi ti Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ojise Olohun, enimimo yoo fi de, oun ni yoo si mu amin buruku yi kuro fun mi'' (won so nipa Islam 93).
      Bakan naa ni ori kokandinlogbon iwe Barnaba, o so bayi pe '' nigba ti Adama duro sori ese re mejeeji, o ri akole kan lara Hawahu ti o tan yanran yanran bi oorun, ti o si so bayi pe: ko si eni ti o leto si ijosin ayafi Olohun, Muhammad (si ni) ojise Olohun'' siwaju ki won to da eni akoko ninu eniyan ni gbolohun yi ti wa ni abe eegun oju baba re, o fi owo pa oju re o si so bayi pe '' ibukun ki o ma ba ojo ti iwo yoo wa saye'' (29).
AWON ERI LAKAYE LORI ODODO IJE ANABI ATI OJISE RE
1-    Ojise Olohun Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je enikan ti ko mo ko ti ko si mo ka, bakan naa awon eniyan re naa je alaimoko alaimoka, eni ti o le ko tabi ka sowon ni aarin awujo won. Eleyi ri be ki iyemeji le kuro fun gbogbo oniyemeji lori oun ti won so kale fun, ki o si ma ba lero wipe oun ni o ko awon oun ti o wu lati odo ara re (ti o wa pe ni oro Olohun). Olohun sope:
 [وَمَا كُنْتَ تَتْلُو مِنْ قَبْلِهِ مِنْ كِتَابٍ وَلَا تَخُطُّهُ بِيَمِينِكَ إِذًا لَارْتَابَ الْمُبْطِلُونَ (48)].
     '' ire ko ke tira kan siwaju re, atipe ire ko fi owo otun re ko o, nitoripe nigba naa awon alaigbagbo won ba se iyemeji'' Q29:48.
Oun ti o mu wa yi ko gbogbo iran larubawa lagara lati mu iru re wa, o si dawon lagara pelu akanlo ede re ati idalawon. Al kurani si ni ise iyanu lailai eyi ti won so kale fun un. Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" ما من الأنبياء نبي إلا وقد أعطي من الأيات ما مثله آمن عليه البشر، وإنما كان الذي أوتيته وحياً أوحاه الله إلي، فأرجو أن أكون أكثرهم تابعاً يوم القيامة "
     '' ko si ikankan ninu awon anabi Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) ayafi ki won fun ni awon amin iru eyi ti awon eniyan ma nni igbagbo si, sugbon eyi ti won fun emi ni imisi ti Olohun mi simi (Al kurani), mo si gbero ko je pe emi ni ma ni omleyin ti o po julo ninu won ni ojo igbende '' (Al Bukhari).
 Pelu wipe awon eniyan je iran ti o da lawon ti won si mo ede pe, Al kurani pewon nija pe ki won mu iru re (Al kurani) miran wa, leyin naa o tun pe won nija ki won mu ogba oro kan (suratu) ti o jo wa. Olohun so bayi pe:
وَإِنْ كُنْتُمْ فِي رَيْبٍ مِمَّا نَزَّلْنَا عَلَى عَبْدِنَا فَأْتُوا بِسُورَةٍ مِنْ مِثْلِهِ وَادْعُوا شُهَدَاءَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ (23)
'' bi e ba si wa ninu iyemeji nipa oun ti Awa so kale fun erusin wa, nje, e mu sura kan wa ti yoo da bi re, ki e si pe awon eleri yin ti ki se Olohun, bi eyin ba je olotito '' Q2:23.
Koda oda gbogbo awon eda lagara ،olohun so bayi pe:
[قُلْ لَئِنِ اجْتَمَعَتِ الْإِنْسُ وَالْجِنُّ عَلَى أَنْ يَأْتُوا بِمِثْلِ هَذَا الْقُرْآنِ لَا يَأْتُونَ بِمِثْلِهِ وَلَوْ كَانَ بَعْضُهُمْ لِبَعْضٍ ظَهِيرًا (88)]
     '' sope: ti awon eniyan ati alijonu ba papo lati mu iru Al kurani yi wa, won ko ni le se iru re, bi apakan won tile ran apakan lowo '' Q17:88.
2-    Itesiwaju re lori ise ipepe re, pelu orisirisi awon wahala ati inira ti o kan lati odo awon eniyan re, eleyi ti o le debi wipe won para po lati pa, ki opin le ba de ba ise ipepe naa. Pelu bee o se suru lori pipepe si esin tuntun ti won fi ran naa, o si ni itemora lori gbogbo oniranran inira, ifiyaje ati ifunlemo ti o ri lati odo awon eniyan re loju ona ise esin. Ti o ba je opuro ti npe ara re ni oruko ti ko je ni, ko ba fi ise naa sile lati dabo bo emi re kuro nibi iparun ti o le sele si ni oju ona ise naa. Latari ilekoko ati ipinnu awon eniyan re lati gbogun ti ati lati pa oun ati ipepe naa run.
      Dr. M.H. Durrani sope: dajudaju igbagbo ododo ati igbayanju ti o lagbara yi, pelu ipinnu emi ati igboya ti Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) fi dari ipepe re titi ti o fi ni aseyori ni igbeyin, je eri pataki lori ije ododo re lori on ti o npepe si. Toripe ti o ba je pe iyemeji nbe ninu emi re lori oun ti o npepe si, iba soro fun lati koju gbogbo awon ipenija ti o lagbara ti o ba pade fun odidi ogun odun. Nje eri mi wa tun nbe bi lori ije olododo re ninu afojusun ati iduro sinsin re nibi iwa rere, ati aponle emi re, gbogbo awon nkan wonyi lo ntoka ti ko ni iye meji ninu wipe ojise Olohun ni se ni ododo, eleyi ni anabi Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba), eni ti o je amin kan pataki nibi awon iroyin re ti ko legbe, ti o si je apejuwe ti o kun fun aponle ati gbogbo daadaa, o si je amin fun ododo ati afokansi. Dajudaju gbogbo igbesiaye re, ironu re, ododo re, iduro sinsin re, iberu Olohun re, ima tore re, adisokan re ati gbogbo aseyori re je eri ti ko ni iyemeji ninu lori wipe anabi Olohun ni se (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Eyikeyi omoniyan ti o ba se iwadi nipa igbesiaye re ati ije ojise re ni yoo jeri pe ojise Olohun ni ni ododo (ike ati ola Olohun ki o ma ba)  Al kurani ti o mu wa fun omoniyan je tira Olohun ni ododo, gbogbo oluseronu ti o ba je onideedee nibi iwadi re nipa ododo ni yoo gba pe olododo ni se''
3-    Ninu eyi ti ko si iyemeji nibe nipe gbogbo eniyan, niti adamo, ni o feran awon oun adun aye bi owo, onjije, onmimu, ati igbeyawo, Olohun ti ola re ga so bayi pe:
 [ زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ الشَّهَوَاتِ مِنَ النِّسَاءِ وَالْبَنِينَ وَالْقَنَاطِيرِ الْمُقَنْطَرَةِ مِنَ الذَّهَبِ وَالْفِضَّةِ وَالْخَيْلِ الْمُسَوَّمَةِ وَالْأَنْعَامِ وَالْحَرْثِ ذَلِكَ مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَاللَّهُ عِنْدَهُ حُسْنُ الْمَآبِ (14)]
     '' a se ni eso fun awon eniyan, ife igbadun ti awon obinrin ati awon omo ati owo pupo niti wura ati fadaka ati awon esin ti won ri itoju ati awon eran osin ati oko. Eyi je igbadun igbesi aye yi, odo Olohun ni abo rere wa '' Q3:14.
      Omoniyan yoo ma gbiyanju ni orisirisi ona, ki owo re le te awon igbadun wonyi ni, sugbon ona ti onikaluku yoo to lati ri igbadun naa yato si ara won. O nbe eni ti yoo rin oju ona eto bakan naa eni ti yoo rin oju ona ti ko leto. Awon eniyan Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni ibere ipepe re gbiyanju lati ba ni afenuko lori awon orisirisi oun igbadun aye ti o ba fe ki awon se fun, ti won si se adehun lati pe gbogbo oun ti awon ba jo fenuko si ninu awon oun ti o ba fe, ti o ba je pe o fe lati je olori, awon setan lati fi se olori. Ti o ba jepe obinrin lo fe, awon yoo fun ni awon ti o rewa julo ninu awon obinrin. Ti o ba si je owo tabi dukia ni o fe, awon yoo fun un. Sugbon gbogbo eleyi pelu mojemu ki o fi esin tuntun ti o npepe si sile ni, o wa dawon lohun pelu igbekele ninu Olohun ati itosona Re wipe '' mi o le fi ipepe yi sile, ayafi ti e ba le mu awijare wa fun mi, gegebi ki e tan ina fun mi latara oorun''. Ti o ba jepe opuro olupe rare ni oun ti ko je ni, iba gba gbogbo awon oun ti won fi lo wonyi, iba si ri gegebi anfani, toripe awon nkan ti won fi lo wonyi je awon oun ti omoniyan ma ndamu fun.
      Dr. M..H. Durrani sope: Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) foju wina wahala ati idamu ni tele ntele fun odidi odun metala ni ilu Makkah, pelu odun mejo ni ilu Madina, o fara da gbogbo awon isoro wonyi lai yese tabi seyemeji, o je onipinnu emi lori afojusun re o si duro sinsin, awon eniyan re gba fun lati je oba le awon lori, ki o si je pe ikapani re ni gbogbo oro ilu yoo wa, nigba ti o ba ti gba lati pa ise ipepe esin ati ije ojise re ti, o ko gbogbo awon itanje wonyi, o si gba lati fara da gbogbo inira ti o ba le ti ibi ipepe esin naa wa. Kin ni oun ti o fa ti o fi gba lati fara da awon inira wonyi, ti o si ko lati gba gbogbo oro, iyi, oba, aponle, idera, igbaye gbadun ati irorun ti won fi lo? Oranyan ni ki omoniyan ronu jinle lori eleyi, ti o ba gbero lati ri idahun si ibere yi.
4-    Ninu eyi ti o gbajumo fun gbogbo eni ti o ba je olori ni wipe gbogbo ola ati ola ilu ni yoo wa ni abe ikapani ati idari re. sugbon ojise nla Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni tie o gba wipe ile aye yi ki se gbere, Ibrahim omo a'lqamah lati odo Abdullah (Olohun ki o yonu si won) sope: ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sun si ori eni ti o si fa ila si lara, mo wa sope: mo fi baba ati iya mi we fun o ire ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), ki lo de ti iwo ko so fun wa ki a ba o te aso si ori re, ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun pe
:" ما أنا والدنيا إنما أنا والدنيا كراكب استظل تحت شجرة ثم راح وتركها"
      '' ile aye ko je nkankan lodo mi, apejuwe mi ninu aye da gegebi arinrin ajo ti o duro sinmi labe igi kan, ti o si tesiwaju irin ajo re ti o fi igi naa sile'' (At tirmidhi).
 Nu'man omo Basheer (Olohun ki o yonu si) sope:
"لقد رأيت نبيكم ﷺ وما يجد من الدقل - رديء التمر - ما يملأ به بطنه.
      '' mo ti ri ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o wa leni ti ko ri nkankan je, koda koje bi tamoru (dabidun) ti o ti baje'' (Muslim).
      Abu Hurayra (Olohun ki o yonu si) sope:
"ما شبع آل محمد ﷺ من طعام ثلاثة أيام حتى قبض.
      '' awon ara ile ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) won ko je ajeyo onje kan fun ojo meta lori ara won titi ti o fi kuro laye'' (Muslim).
Gbogbo eleyi sele pelu pe gbogbo erikusu ile larubawa nbe labe ikapani re, ti o tun jepe oun naa ni okunfa gbogbo oore ti o de ba awon musulumi, sugbon a ma waye ti awon ara ile re ko ni ri oun ti won yoo je ni awon igba miran. Iyawo re, Aisha (Olohun ki o yonu si) sope:
" أن النبي ﷺ اشترى طعاما من يهودي إلى أجل فرهنه درعه".
     '' ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ra onje ni owo yehuudi kan o si fi aso ogun re dogo (sodo re)'' (Al Bukari ati Muslim).
      Awon isele wonyi ko tumo si wipe ko si ikapani fun lati ri awon oun ti o fe, nigba ti o si je pe gbogbo oro ati ola ni won ma ngbe wa ba ni aye re ninu mosalasi, ti o si jepe ibe naa ni yoo ti pin gbogbo re fun awon alaini ati talaka. Bakan naa ni o wa ninu awon omoleyin re awon oloro ti won ni owo ati dukia repete, tiwon si ma n se idije laarin ara won lori sise ise sin in, won ma nna gbogbo oun ti won ni nitori re, sugbon ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) mo paapaa ile aye, o si ma nso bayi pe:
"والله ما الدنيا في الآخرة إلا مثل ما يجعل أحدكم إصبعه هذه - وأشار بالسبابة في اليم-البحر-، فلينظر بما ترجع"
     '' mo fi Olohun bura, apejuwe (oore) ile aye si (oore) orun da gegebi apejuwe ki enikan ninu yin ti ika re bo inu omi okun, ki o wa wo oun ti yoo mu jade nibe'' (Muslim).
      Lady E. cobold so ninu iwe re '' irin ajo lo si ilu Makkah (London1993) '' wipe: pelu wipe Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je asiwaju fun erikusu ile larubawa…. Ko sare ki o fun ara re ni alaje (oruko) orisirisi ki a to wa sope siseku re, bikosepe o gba tito pelu jije ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ati olumojuto oro awon musulumi, o ma nse itoju ile re fun ra re, o si ma ntun bata re se fun ra re. Olutore alanu ti o ma na oun ti o ba ni fun gbogbo eniyan, ko si eni ti o nde odo re ti yoo lo lowo ofo, bio tile jepe oun ti o ni ko to fun bukata tie naa''
5-    Awon isele ti o lagbara ma nsele si ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni igba miran ti yoo bukata si alaye lori re sugbon ti ko ni si ona abayo fun toripe oro Olohun koti so kale fun lori re, ti yoo si wa ninu ibanuje fun igba pipe titi ti oro Olohun yoo fi so kale. Ninu awon isele bayi ni eyi ti won fi paro mo Aisha (Olohun ki o yonu si) wipe o se agbere, ti won si gbero latara re lati bu enu ate lu idile ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Oro naa wa be fun odidi osu kan gbako, ti awon ota si nso isokuso nipa re, ti won si ntenu bole ti won se abosi ati oro eyin lori re titi ti Olohun fi so oro re kale, ti o si fo Aisha (Olohun ki o yonu si) mo kuro nibi enu ate ti won fi nkan an. Ti o ba je pe opuro olupe ara re ni oun ti ko je ni, i ba wa ona abayo si oro naa fun ra re lasiko, sugbon o je eni ti ki so ti ara re sugbon oun ti Olohun ba ran ni ma nso.
6-    Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ko gbe ara re si ipo ti o ju ti omoniyan lo. O korira ki awon eniyan ba lo ni ibalo ti aponle re ti koja ala. Anas omo Malik sope:
: لم يكن شخص أحب إليهم من رسول الله ﷺ ، قال: "وكانوا إذا رأوه لم يقوموا لما يعلمون من كراهيته لذلك.
     '' ko si enikan ti awon feran ju ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lo, o sope '' won ki dide fun nigba ti o ba nbo toripe won mo pe o korira be ''(At tirmidhi).
     W. Irving sope: pelu gbogbo isegun ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni ni awon oju ogun orisirisi, eleyi ko ko igberaga tabi ijora eni loju ba rara, gbogbo ogun ti o ja pata ni o ja nitori esin Islam ti ki se nitori anfani ti ara re. Koda nigba ti owo re te ola ati ola tan, ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) koye kogbo leni ti o re ara re sile ti o si ngbe igbesi aye ti o rorun. O korira ki won dide lati ki nigba ti o ba de si aarin won, bo tile jepe erongba re ni lati fi awujo ti o lakun laka lele, ti yoo je orilede Islam, o dari awujo naa pelu deedee, ti ko si ronu lati gbe eto ijoba re sile fun awon molebi re.
7-    Apakan awon oro Al kurani lo so kale fun ibawi ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) latara awon isesi tabi iwa kan ti o hu, ni apere: oro Olohun ti o so bayi pe:
[يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَا أَحَلَّ اللَّهُ لَكَ تَبْتَغِي مَرْضَاتَ أَزْوَاجِكَ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ (1)]
     '' ire anabi, kinise ti o so oun ti Olohun se leto fun o di eewo (fun ara re)? ire fi nwa idunnu awon iyawo re? Olohun je oludarijin onike '' Q66:1.
     Eleyi sele nitoripe ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se ni eewo fun ara re lati la oyin nitori apakan ninu awon iyawo re, Olohun bawi lori re toripe o se oun ti Olohun se leto fun di eewo fun ara re. Ati oro Olohun ti o sope:
 [عَفَا اللَّهُ عَنْكَ لِمَ أَذِنْتَ لَهُمْ حَتَّى يَتَبَيَّنَ لَكَ الَّذِينَ صَدَقُوا وَتَعْلَمَ الْكَاذِبِينَ (43)]
     '' Olohun ti se amojukoro fun o! kinise ti o fi nyonda fun won (pe ki won gbele) titi ti awon eni ti won so ododo yoo fi han si o, ti ire naa yoo fi mo awon opuro '' Q9:43.
     Olohun ba ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) wi ninu ese oro yi lori ikanju nibi gbigba awijare asan ati iro lowo awon sobe selu, awon ti won sa seyin loju ogun Tabuki, ti o si gba ipe won lai se idanwo fun won lati fi mo eni ti nparo ninu won yato si olododo.
 Bakan naa oro Olohun ti o so bayi pe:
[مَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَنْ يَكُونَ لَهُ أَسْرَى حَتَّى يُثْخِنَ فِي الْأَرْضِ تُرِيدُونَ عَرَضَ الدُّنْيَا وَاللَّهُ يُرِيدُ الْآخِرَةَ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ (67) لَوْلَا كِتَابٌ مِنَ اللَّهِ سَبَقَ لَمَسَّكُمْ فِيمَا أَخَذْتُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ (68)]  
     '' ko to fun Anabi kan ki imuni leru logun ma be fun un, ayafi ti o ba ja titi yoo fi segun lori ile yanyan, eyin nfe igbadun ti aye, Olohun si nfe fun yin (oore) ti orun, be si ni Olohun ni Oba ti o tobi, Ojogbon.\\ Ti ko ba si ti ase kan ti o ti gba iwaju lati odo Olohun ni, iya ti o tobi iba fowo kan yin nipa oun ti e gba '' Q8:67&68.
Aisha (Olohun ki o yonu si) sope:
" لو كان محمد ﷺ كاتماً شيئاً مما أنزله الله لكتم هذه الآية "
     '' ti o ba jepe Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba fe lati fi nkankan pamo ninu oun ti Olohun so kale fun ni, iba fi ese oro yi pamo
 [وَتُخْفِي فِي نَفْسِكَ مَا اللَّهُ مُبْدِيهِ وَتَخْشَى النَّاسَ وَاللَّهُ أَحَقُّ أَنْ تَخْشَاهُ]
     '' atipe ire (Anabi) nfi pamo sinu okan re oun ti Olohun yoo se afihan re, o wa nberu awon eniyan beeni Olohun ni o leto pe ki o beru Re '' Q33:37. (Al Bukari ati Muslim).
     Ati oro Olohun ti o so pe:
[لَيْسَ لَكَ مِنَ الْأَمْرِ شَيْءٌ.....  
     '' ko si eyi ti o kan o ninu oro naa, oun iba dari jinwon tabi ki o jewon niya, dajudaju alabosi ni won '' Q3:128.
Ati oro Olohun ti o so bayi pe:
  [عَبَسَ وَتَوَلَّى (1) أَنْ جَاءَهُ الْأَعْمَى (2) وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّهُ يَزَّكَّى (3)].
     '' O faju ro, o si yi pada \\ Nitoripe afoju naa wa ba \\ Atipe kinni o le mu o mo amodaju pe oun le se mimo '' Q80:1-3.
      Ti o ba je opuro olupe ara re ni oun ti ko je ni, ko ba ti si awon ese oro wonyi ti ibawi re wa nibe ninu Al kurani.
      Lightner so ninu iwe re '' Esin Islam '' wipe: ni igba miran Olohun yoo so awon ibawi ti o le kale fun ojise re Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba), toripe o gbe oju re kuro lodo alaini ti o je afoju lati ba eni ti o je oloro ati abiyi lawujo soro, ese oro yi ko pamo rara, ti o ba jepe bi awon alaimokan elesin kirisiteni se nso nipa re ni, iru ese oro bayi ko ba ti seku sinu Al kurani''.
8-    Ninu awon eri ti o lagbara pupo lori jije ododo ije ojise Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ati ije ododo oun ti o mu wa ni ogba oro (suratu) Al masad Q 111. Eyi ti nso lai ni iye meji ninu wipe egbon baba re Abu Lahab yoo wo ina. Ogba oro yi so kale ni ibere ipepe re (ike ati ola Olohun ki o ma ba). Ti o ba je opuro olupe ara re ni oun ti ko je ni, ko ni so iru idajo ti ko ni iyipada bayi, toripe o seese ki egbon baba re yi pada ki o si di musulumi.
     Dokita Gary Miller so bayi pe: okunrin ti won npe ni Abu Lahab yi korira esin Islam ni ikorira ti o lagbara, debi wipe o ma ntele Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) kaakiri lati fi enu abuku kan oun ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba nso, ti o ba ti ri ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o nba awon eniyan ti won je ajoji soro, yoo se suru titi ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) yoo fi pari oro re pelu won, yoo si lo ba won yoo si bi won leere wipe kin ni Muhammad ba yin so?, ti o ba so fun yin pe dudu ni e gba pe funfun ni, ti o ba si so fun yin pe osan ni, e gba pe ale ni.         Erongba re ni lati ma tako ohunkohun ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba ti so, ki o si ma ko iyemeji si okan awon eniyan lori oro re. Odun mewa siwaju ki Abu Lahab to ku ni ogba oro ti o soro nipa re (Al masad) ti so kale. Suratu yi nse afirinle wipe dajudaju inu ina ni Abu Lahab yoo wo, ti o tumo si pe ko ni gba Islam titi ti yoo fi ku.
      Laarin odun mewa gbako, ko si nkankan ti o ye ki Abu lahab se ju ki o wa si iwaju awon eniyan ki o si sope: Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope mi o ni di musulumi atipe inu ina ni ma wo, sugbon nisinsinyi mo wa nkede Islam mu mi bayi, wipe mo fe di musulumi !! ki le ri si? nje olododo ni Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) abi opuro lori oun ti nso? atipe nje oro Olohun lo nde wa ba abi iro? Sugbon Abu Lahab ko se eleyi bikosepe atako ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni o tun fi gbogbo ise re se.
      Abu Lahab ko yapa on ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so lori re lori pe yoo wo ina ni ojo ikeyin. Fun odidi odun mewa gbako Abu Lahab ko di musulumi koda ko dogbon pe oun yoo di musulumi. Fun odun mewa o ni anfani lati dan esin Islam wo laarin iseju kan pere! sugbon tori wipe oro yi ki se ti Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) bikosepe oro Olohun ti o ni imo koko, ti o si mo pe Abu Lahab ko ni di musulumi lailai.
-    Bawo ni Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se mo pe Abu Lahab yoo se afirinle oun ti nbe ninu ogba oro naa ti ko ba je o sokale lati odo Olohun ti ola re ga?
-    Bawo ni okan re yoo se bale fun odidi odun mewa gbako lori wipe ododo ni oun ti oun so, ti ko ba je pe o mo imisi ni lati odo Olohun?
Ki eniyan gbe iru ipeni nija ti o lagbara bayi kale, ko tumo si nkankan ju pe odo Olohun ni imisi re ti wa.
تَبَّتْ يَدَا أَبِي لَهَبٍ وَتَبَّ (1) مَا أَغْنَى عَنْهُ مَالُهُ وَمَا كَسَبَ (2) سَيَصْلَى نَارًا ذَاتَ لَهَبٍ (3) وَامْرَأَتُهُ حَمَّالَةَ الْحَطَبِ (4) فِي جِيدِهَا حَبْلٌ مِنْ مَسَدٍ (5)
        '' Owo Abu Lahab (baba ina) mejeeji ti sofo, o (un na) si sofo \\ Awon oro (owo) re ati ise re ti o se ko ni se ni oore kankan \\ yoo wo ina ti njo geregere \\ Ati iyawo re a ru igi isepe elegun \\ Ti o si ni okun lilo (masad) lorun ''. Q111: 1-5.
9-    Oruko Ahmad waye ni awon aaye kan ninu Al kurani dipo Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti a mo si oruko ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), gegebi oro Olohun to sope:
 وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِنْ بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ فَلَمَّا جَاءَهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ قَالُوا هَذَا سِحْرٌ مُبِينٌ (6)
     '' atipe (se iranti) nigbati Isa omo Mariyama sope: eyin omo Israila, dajudaju emi je ojise Olohun si yin ti o njeri ododo si ohun ti o ti siwaju ninu Taoreta mo si je olufun (yin) niro idunnu nipa ojise kan ti yoo de leyin mi, ti oruko re yoo si ma je Ahmad, sugbon nigba ti o de wa ba won pelu alaye ti o yanju, won so pe idan kan ti o han gbangba ni eyi '' Q61:6.
     Ti o ba je olupe ara re ni oun ti ko je ni, oruko re ko ni han ninu Al kurani.
10-    Dajudaju esin ti o muwa koye kogbo leyi ti nbe titi di oni yi, beeni awon eniyan won o si ye leni ti nwo inu esin naa ni onka repete, won si ngbola fun lori awon yoku, pelu bi awon eniyan se kere ni inawo si ipepe re, yala ni ti owo nina ni tabi ni ti afara se. Awon igbiyanju ti awon eniyan se lati polongo esin Islam ko to nkankan ninu igbiyanju ti awon ota esin se lati fi da oju re bole ati lati ba oruko ati aworan esin naa je lodo awon eniyan. Sugbon esin naa duro sinsin bi apata, toripe Olohun Oba ti ola re ga ti la siso esin na borun lati odo ara re, oro Olohun so bayi pe:
 إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ
     '' dajudaju Awa ni A so iranti naa kale Awa naa si ni Oluso fun un '' Q15:9.
     Th. Carlyle so, ninu (won so nipa Islam) ti o je ede oyinbo, nipa Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba): nje e ri ri ki opuro eniyan ni ikapa lati fi esin ti o je esin iyanu lele ri? iru eni bayi ko le ko ile Alamo! Nigba ti ko ba je onimimo nipa awon eroja oun ikole ati bawo ni a se nlo won lati ko ile, ise iru eniyan bayi yoo je atori kodi ati dida awon eroja ikole papo nikan. Ko seese fun iru ile bayi ki o ma seku fun odidi ogorun odun mejila, ki awon onka ti ko kere ni egbe gberu lona egberun meji si ma gbe ninu ile naa, eyi ti o to fun iru ile bayi ni ki gbogbo awon origun re kookan dawole ki o si pare gegebi igba ti won kuku ko rara. Eyi ti o dami loju ni wipe o je dandan fun omoniyan ki o ma gbe gbogbo igbese re patapata ni ibamu si ilana adamo, bi beeko owo re ko ni te afojusun re…. iro ti awon alaigbagbo nfon ka, ti won si se loso ti awon eniyan fi wa rope ododo ni…. adanwo ni ki eniyan tan awujo tabi ijo awon eniyan je pelu awon oro ti ko lese nle wonyi''.
      Won dabobo Al kurani, leyin idabobo lati odo Olohun, pelu kiko sile ati hiha sori awon eniyan ni iran kan si iran keji, toripe didabobo o, kike re, kiko re ati fifi ko elomiran ninu awon ti awon musulumi ni akolekan re pupo ni, ti won si ma nse ifigagbaga lori re, lati ri oore eyi ti ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) salaye pelu oro re pe:
" خيركم من تعلم القرآن وعلمه "
     '' eni ti o loore ju ninu yin ni eni ti o keko Al kurani ti o si tun fi ko elomiran '' (Al Bukhari).
      Ninu isesi awon eniyan ni wipe won ti gbiyanju lori sise alekun, adinku tabi yiyi awon oro inu re pada, sugbon gbogbo awon igbiyanju wonyi ni o fori sonpon, eleyi rorun, toripe kiakia ni yoo foju han ti yoo si da yato gedegede si awon ese oro Al kurani Alaponle.
      Bakan naa ni (As sunnah) awon egbawa oro ojise nla Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o je ipile elekeji fun esin Islam. Won dabo bo oun naa ni ipase awon eniyan ti won je olododo alafokantan onideedee, won fi ara sile fun wiwa awon oro ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), won si se afirinle awon to fese rinle (As saheeh) ninu won, won si salaye awon ti o le (Ad doheef) nibe, won si yo awon ti o je adapa iro (Al mawdu') jade ninu re. Eni ti o ba ka awon iwe ti o je iwe oro ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o ni akolekan pelu awon hadith naa yoo ri paapaa igbiyanju ti awon eniyan wonyi se lati dabo bo gbogbo oun ti o wa lati odo ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti ko si ni iyemeji lokan lori oun ti o ba fese rinle lati odo ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba).
      Michael Hart so ninu iwe re '' iwadi nipa ogorun akoko '' wipe: Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se agbekale ati ipolongo okan ninu awon eekan esin lagbaye, ti o si wa di okan pataki ninu awon eekan asiwaju oloselu fun gbogbo agbanlaye, ni asiko ti a wa yi leyin oun ti o fe to ogorun odun metala ti o ti kuro laye, dajudaju oripa re si nni agbara si ''.
11-    Ije ododo, ilalafia ati iba gbogbo igba ati asiko mu awon ipile ti o mu wa, ati awon abajade rere ti o mu anfani lowo, ti o si kun fun ibukun, ti o njade latara lilo awon ipile wonyi, lo njeri lori wipe oun ti o mu wa je isokale (imisi) lati odo Olohun ti ola re ga. Bakan naa, nje nkankan wa nbe ti o se leewo fun Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) lati je ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o ran lati odo Re, nigba ti o si jepe o ti ran awon Ojise ati Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) repete siwaju re? ti o ba jepe idahun si ibeere yi ni pe ko si oun ti o se lewo lati je ojise ati anabi Olohun re, ni abala ti lakaye ati ni ti esin, ki wa ni oun ti o fa ti won fi ntako ije ojise ati anabi re si gbogbo eniyan patapata, ti o si jepe won gba ije ojise awon Anabi (ike ati ola Olohun ki o ma ba won) ti won siwaju?
12-    Dajudaju awon ilana, eto ati ofin ti esin Islam muwa fun omoniyan lati ori awon ojise nla Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni abala ibesepo laarin omoniyan, igbeyawo, ogun jija, eto oro aje, eto iselu, ilana ijosin ati beebee lo, lo ko omoniyan lagara nibi mimu iru awon ilana ati eto ti o moyan lori bayi wa. Iwo eniyan mi, nje o wa balakaye mu ki a so pe eniti ko le ko ti ko le ka ni o mu ilana ati eto ti o kun keke, ti o si se eto gbogbo aye ti o si gun rege  bayi wa? se ki wa se pe eleyi ntoka lori ije ododo ije anabi re ati ije ojise re bi, atipe ko so ti ara re rara?
13-    Atipe ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ko bere ise ipepe re ni gbangba ayifi igba ti o to pe omo ogoji odun ti o kuro ni ipo odo ati akobere ije odo pelu agbara, ti o si bo si ipo agba ipo pelepele ati isinmi ati sise jeje.
      (Th. Carlyl) so ninu iwe re (Awon Akoni) wipe: ninu awon oun ti o gbe oro awon eni ti won nsope Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki se olododo ni abala ije ojise re subu ni pe, o lo ibere odo ati agbara idagbasoke re ni isemi pelepele ati ifarabale (pelu iyawo re Khadijah), ni aarin asiko yi ko pariwo ipepe kankan, leyi ti o sepe ipepe iru asiko yi ni opolopo igba ma wa lori arihan, sekarimi, iyi ati iwa agbara….ko se eleyi ayafi leyin igba ti o ti kuro ni odo ti o si ti nwo ipo agba, leyin igba ti iru soke emi ti ma njo gere ti sun, igba yi ni o wa gbero lati fi oun nla pataki kan lele ''.
      R. Landau so ninu iwe re (Esin Islam ati Iran Larubawa), erongba Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je eyi ti o banileru lagbara, erongba ti ko si fun awon eniyan yepere ti imotara eni nikan joba lemi won, eleyi ni iroyin ti apakan awon onkowe akoko lati ile oyinbo fi royin ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o wa lati inu iran larubawa, wipe o gbero lati ni aseyori lori re pelu igbiyanju re. Dajudaju ododo emi ti Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni nibi pipe iwo ije ojise re, pelu igbagbo pipe ti awon omoleyin re ni si oun ti won so kale fun ni imisi ati igbidanwo awon iran iran, gbogbo eleyi nje ki o ye wipe ko ba lakaye mu lati so pe eletan ni Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ni eyikeyi ona. Nigba ti o je pe ko si ninu itan omoniyan wipe esin ti won gbe lori etan wa lo isemi ti o gun repete bayi ri. Esin Islam nisinsinyi ti lo oun ti ko kere ni egberun kan ati ogorun odun meta (1300). Koda odoodun ni onka awon omoleyin tun npo si. Ti o si je wipe a ko ri ninu iwe itan apejuwe kan pere nipa eni ti o lo etan se  ipepe r  ti si nseku laarin awon eniyan, yala oba kan ninu awon oba alagbara aye, tabi olaju ti o wa gbayi ju awon olaju yoku lo ''

AWON ETO TI O SOPO MO JIJERI PE MUHAMMAD (IKE ATI OLA OLOHUN KI O MA BA) OJISE OLOHUN NI
1-    Gbigba wipe ojise Olohun ni lododo, ti won ran si gbogbo omoniyan patapata, ki se awon eniyan re nikan ni Olohun ran si tabi asiko re nikan, bikose o je ojise Olohun si gbogbo eda, lai fi ti aye tabi asiko se, titi ti aye yoo fi pare. Olohun sope:
[ تَبَارَكَ الَّذِي نَزَّلَ الْفُرْقَانَ عَلَى عَبْدِهِ لِيَكُونَ لِلْعَالَمِينَ نَذِيرًا (1)]
     '' Ibukun ni fun Eniti O so oluse onpinya ododo kuro ni ara iro kale fun erusin Re ki o le ba je olukilo fun gbogbo eda '' Q25:1.
2-    Ini adisokan wipe Olohun dabo bo lori ise ti o je lati odo Re Oba onibukun ti ola re ga. Olohun so bayi pe:
وَمَا يَنْطِقُ عَنِ الْهَوَى (3) إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْيٌ يُوحَى (4)
     '' Atipe ki nso oro ife inu \\ oun ko je kinikan bikose ise ti a ran an (si i) '' Q53: 3&4.
     Sugbon awon isesi re miran oun naa ko yato si awon omoniyan yoku nibe. O ma se ngbiyanju nibi awon isesi ati idajo re, latara oro ti o so bayi pe:
"إنكم تختصمون إلى ولعل بعضكم أن يكون ألحن بحجته من بعض فأقضي له على نحو مما أسمع منه، فمن قطعت له من حق أخيه شيئاً فلا يأخذه، فإنما أقطع له قطعة من نار"
     '' eyin yoo ma ko aigbora eniye wa ba mi, ti o si seese ki apakan yin da lawon nibi awijare re ju apakeji lo, kin wa dajo gbe lori oun ti mo gbo lenu re, enikeni ti mo ba gbe nkankan fun ninu iwo enikeji re ko gbodo gba o, toripe ipin kan ninu ina ni mo gbe fun un '' (Al Bukari ati Muslim).
3-    Ini adisokan wipe gbigbe dide re je ike fun gbogbo eniyan patapata. Olohun ti ola re ga so bayi pe:
وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ (107)
     '' Atipe Awa ko ran o nise bikosepe ki o le je ike fun gbogbo aye '' Q21:107.
     Ododo ni oro Olohun, toripe ike ni o je ni gbogbo oun ti ike ma ntumo si. O mu awon eda kuro nibi ima josin fun eda (egbe won) lo si ibi ijosin fun Oluwa Adeda, o mu won kuro nibi esin abosi losi ibi deedee esin Islam, o mu won kuro nibi ifun pinpin ile aye lo sibi aye ti o fe ni orun.
4-    Ini adisokan ti o daju wipe oun ni igbeyin, opin ati eni ti o lola julo ninu awon ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba won), ko si ojise tabi anabi kan ti yoo tun waye layin re mo. Olohun ti ola re ga so bayi pe:
مَا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَا أَحَدٍ مِنْ رِجَالِكُمْ وَلَكِنْ رَسُولَ اللَّهِ وَخَاتَمَ النَّبِيِّينَ
     '' Muhammad ki se baba enikankan ninu awon okunrin yin, sugbon o je ojise Olohun ati ikeyin awon Anabi, Olohun si je onimimo nipa gbogbo nkan '' Q33:40
5-    Ini adisokan ti o daju wipe esin ti pari o si ti pe lori re, ko si anfani fun afikun tabi ayokuro ninu re mo, Olohun ti ola re ga so bayi pe:
الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا
     '' Loni yi Mo se esin yin ni pipe fun yin, atipe Mo se asepe idera Mi leyin lori atipe Mo yonu si Islam ni esin fun yin '' Q5:3.
      Eleyi je akiyesi ati afojuri kan pataki, nipa bi Islam se je esin kan ti o ko gbogbo agbegbe isemi aye sinu: eto oselu, oro aje, eto awujo ati eto iwa, esin Islam je esin ati oselu ni gbogbo itunmo re.
 Kwelem, ti o je olurori omo ile oyinbo, so ninu iwe re (Adisokan Islam) ni oju ewe 119-120 wipe: awon idajo Al kurani ko mo lori awon oranyan eko ati esin nikan…. O je ofin gbogbogbo fun gbogbo agbaye Islam, o je ofin ti o ko ilana oselu, tita ati rira, ogun jija, isofin, idajo odaran ati ifiyajeni, bakan naa o tun je ilana esin ti gbogbo igbese kookan ninu awon igbese esin ati  isemi aye nlo ni ibamu si itosona re, lati ibi didabo bo emi titi ti o fi de ibi didabo bo ara, lati ibi didabo bo iwo ara ilu lo sibi didabo bo iwo enikookan, lati ibi anfani enikookan lo sibi anfani awujo, lati ibi gbigbesan nile aye titi ti o fi debi gbigbesan ni orun…..lori eleyi, Al kurani je iwe kan ti o yato ni abala igbekale si awon iwe esin kirisiteni alaponle n ti ko si ipile esin kankan ninu re, bikosepe o kun fun awon itan aroso ti ko nidi ati idaru dapo ti o lagbara nibi oro ijosin…. Eyi ti ko mu lakaye dani ti ko si ni oripa ''
6-    Ini adisokan ti o daju wipe Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pe gbafipamo ti Olohun la bo lorun, o si jise ti won ran, o si gba awon ijo re ni imoran, ko si oun kankan ti o je oore ayafi ki o juwe re fun won ki o si pawon lase re, ko si aburu kan ayafi ki o wa won ni isora nibe ki o si ko o fun won, toripe ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) so ni Hajj idagbere nigba ti o nba awon eniyan ti won po lonka soro bayi pe '' eteti, nje mo jise?'' won dahun pe: beeni, o si sope '' Olohun jeri si '' (Al Bukari ati Muslim).
7-    Ini adisokan wipe ilana esin ti Olohun so kale fun nikan naa ni yoo je atewogba lodo Olohun leyin ti Olohun ti gbe dide, a ko gbodo josin fun Olohun pelu ilana miran ti o yato si ilana re, atipe Olohun ko ni gba oun ti o ba yato si, o ri re ni Olohun yoo se isiro eda le lori. Olohun so bayi pe:
 وَمَنْ يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَنْ يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ
     '' Enikeni ti o batun wa esin kan ti o yato si Islam, A ki yoo gba a lowo re, ni ojo ikeyin oun yoo si wa ninu awon eni ofo '' Q3:85. Ati oro ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o so bayi pe:
 " والذي نفس محمد بيده لا يسمع بي أحد من هذه الأمة يهودي ولا نصراني ثم لم يؤمن بالذي أرسلت به إلا كان من أصحاب النار " (صحيح مسلم)
     '' mo fi eni ti emi Muhammad nbe lowo re bura wipe enikeni ko ni gbo iro mi ninu ijo yi, elesin Yehudi lo je ni tabi elesin Kirisiteni, ti ko wa gba oun ti won fi ran mi gbo, ayafi ki o je omo ina '' (Muslim).
8-     Itele ase re ni ibamu si oro Olohun ti o sope:
وَمَنْ يُطِعِ اللَّهَ وَالرَّسُولَ فَأُولَئِكَ مَعَ الَّذِينَ أَنْعَمَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ مِنَ النَّبِيِّينَ وَالصِّدِّيقِينَ وَالشُّهَدَاءِ وَالصَّالِحِينَ وَحَسُنَ أُولَئِكَ رَفِيقًا (69)
     '' enikeni ti o ba tele Olohun ati Ojise na, awon wonyi nbe pelu awon eni ti Olohun se idera fun ninu awon Anabi, ati awon olododo ati awon eleri otito ati awon oniwa rere, awon wonyi ni o dara ju ni egbe rere '' Q4:69.
     Eleyi nipe mimo tele ase re ati jijina si awon oun ti o ba ko, toripe Olohun ti ola re ga so pe:
وَمَا آتَاكُمُ الرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَاكُمْ عَنْهُ فَانْتَهُوا وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
     '' Atipe ohunkohun ti ojise naa ba fun yin e gba a, ohunkohun ti o ba si ko fun yin e ko o, ki e si paya Olohun dajudaju Olohun le koko lati fi iya jeni '' Q59:7.
     Olohun Oba aleke ola salaye awon oun ti o le je abajade iyapa ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), O so bayi pe:
[وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُ يُدْخِلْهُ نَارًا خَالِدًا فِيهَا وَلَهُ عَذَابٌ مُهِينٌ (14)]
     '' enikeni ti o ba ko ti Olohun ati Ojise Re, ti o si rekoja enu ala Re, oun yoo mu wo inu ina, yoo si ma gbe ibe lo titi, iya abuku yoo si ma be fun '' Q4:14.
9-    Iyonu si idajo re ki eniyan si ma tako ilana ati sunnah re, toripe oro Olohun ti ola Re ga sope:
[فَلَا وَرَبِّكَ لَا يُؤْمِنُونَ حَتَّى يُحَكِّمُوكَ فِيمَا شَجَرَ بَيْنَهُمْ ثُمَّ لَا يَجِدُوا فِي أَنْفُسِهِمْ حَرَجًا مِمَّا قَضَيْتَ وَيُسَلِّمُوا تَسْلِيمًا (65)]
     '' sugbon won ko se be, mo fi Oluwa re bura, won ko ni igbagbo titi ti won yoo fi fi o se onidajo nipa oun ti won nse ariyanjiyan si laarin won, leyin naa ti won ko ri oun ti okan won ko ninu oun ti o da lejo, ti won si gba towo tese '' Q4: 65.
      Bakan ni pe eniyan gbodo gbola fun ilana re ati idajo re lori oun ti o yato si ninu awon ofin, idajo, iseto ati ilana, tori oro Olohun ti ola re ga ti o sope:
أَفَحُكْمَ الْجَاهِلِيَّةِ يَبْغُونَ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ حُكْمًا لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ (50)
     '' idajo igba aimokan na ha nwa bi? Tani eni ti o dara ju Olohun lo ni idajo fun awon eniyan ti o mo amodaju (nipa Re) Q5:50.
10-    Ima tele sunnah re, nitori oro Olohun ti o so bayi pe:
قُلْ إِنْ كُنْتُمْ تُحِبُّونَ اللَّهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللَّهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ (31)
     '' Wipe: ti eyin ba je eni tio feran Olohun, e tele mi, Olohun yoo feran yin, yoo si fi ori awon ese yin jin yin, Olohun Alaforijin Alanu '' Q3:31.
     Ati mima tele igbese re ati ririn lori ilana ti o fi lele, ki o si je pe oun ni yoo je apere ti o dara julo lati wo kose, Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
[لَقَدْ كَانَ لَكُمْ فِي رَسُولِ اللَّهِ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِمَنْ كَانَ يَرْجُو اللَّهَ وَالْيَوْمَ الْآخِرَ وَذَكَرَ اللَّهَ كَثِيرًا (21)]  
     '' Dajudaju ikose rere nbe fun yin lara Ojise olohun fun eni ti nberu Olohun ati ojo ikeyin ti o si nranti Olohun ni opolopo (igba) '' Q33:21.
      Ikose ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) pepe lo sibi ki eniyan mo itan re ko si ko eko re, ki o le ni anfani pipe lati kose re. zaynu l abidini ti se Aliy omo Husaen omo Aliy omo Abu Talib (Olohun ki o yonu si won) sope: a ma nko (awon eniyan) nipa awon ogun ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gegebi a se ma nko won ni ogba oro (suratu) Al kurani. (Al bidayah wa An nihayah ti Ibn Katheer 3 \ 242).
      Oro ogun je  apakan ninu itan ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba).
11- Gbigbe ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si ipo ti Olohun gbe si, lai ni aseju ninu tabi aseeto, toripe ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) sope:
" لا تطروني كما أطرت النصارى ابن مريم فإنما أنا عبده فقولوا عبد الله ورسوله "
     '' e ma yinmi ni eyin ayinju gegebi bi awon kirisiteni se yin omo Mariyamo (jesu) ni eyin ayinju, erusin Olohun ni mo je, e  pe mi ni erusin Olohun ati ojise Re '' (Al Bukhari).
11-    Mimo se adua fun un ni gbogbo igba ti won ba ti daruko re, toripe Olohun ti ola Re ga sope:
[إِنَّ اللَّهَ وَمَلَائِكَتَهُ يُصَلُّونَ عَلَى النَّبِيِّ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا صَلُّوا عَلَيْهِ وَسَلِّمُوا تَسْلِيمًا (56)]
     '' Dajudaju Olohun ati awon Malaika re nfi ibukun fun Anabi, eyin ti e gbagbo ni ododo e ma toro ibukun fun un, ki e si ki ni kiki alafia '' Q33:59.
     Ati oro re ti o sope:
" البخيل الذي  ذكرت عنده فلم يصل علي"
     '' eni ti o je ahun ni eni ti won daruko mi leti re ti ko si toro ibukun fun mi '' (At tirmidhi).
12-    Inife re pelu mimo se aponle re, pelu mima ti ife re siwaju ife gbogbo eda yoku, toripe oun ni o tun ni ola lori awon eda leyin Olohun tori wipe oun ni okunfa imona omoniyan lo sibi esin ododo, eyi ti o ko orire aye ati orun sinu. Atipe oro Olohun ti ola Re ga so bayi pe:
[قُلْ إِنْ كَانَ آبَاؤُكُمْ وَأَبْنَاؤُكُمْ وَإِخْوَانُكُمْ وَأَزْوَاجُكُمْ وَعَشِيرَتُكُمْ وَأَمْوَالٌ اقْتَرَفْتُمُوهَا وَتِجَارَةٌ تَخْشَوْنَ كَسَادَهَا وَمَسَاكِنُ تَرْضَوْنَهَا أَحَبَّ إِلَيْكُمْ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ وَجِهَادٍ فِي سَبِيلِهِ فَتَرَبَّصُوا حَتَّى يَأْتِيَ اللَّهُ بِأَمْرِهِ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ (24)]
     '' Wipe: ti o ba jepe awon baba yin, ati awon omo yin ati awon omo iya yin ati awon ibatan yin ati awon dukia yin ti e ti kojo ati awon oja kan ti e nberu kikuta re ati awon ibugbe ti e nyonu si، wu yin ju Olohun lo ati Ojise Re, ati ijagun si oju ona Re, nigba naa e ma reti titi ti Olohun yoo fi mu ase Re de, Olohun ko ni fi ona mo awon obileje '' Q9:24.
     Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) papa ti salaye awon oun ti o romo inife re ninu oro re fun arakunrin ti o bi leere wipe:
: يا رسول الله متى الساعة ؟ فقال له عليه الصلاة والسلام: " ما أعددت لها " ؟ فكأن الرجل استكان ثم قال: "يا رسول الله، ما أعددت لها كبير صيام ولا صلاة ولاصدقة، ولكني أحب الله ورسوله, قال له عليه الصلاة والسلام:" أنت مع من أحببت "
     '' ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), igbawo ni ojo ikeyin? Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si dahun wipe '' kini o ti pa lese sile fun? o dabi pe itiju mu arakunrin naa, o si dahun wipe: ire Ojise Olohun mi o palemo fun pelu awe tabi irun tabi itore aanu ti o po, sugbon mo nife Olohun ati Ojise Re, Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) si da lohun wipe '' iwo yoo ma be pelu eni ti o nife '' (Al Bukari ati Muslim).
 Ati oro re ti o sope:
:" ثلاث من كن فيه وجد بهن حلاوة الإيمان: أن يكون الله ورسوله أحب إليه مما سواهما، وأن يحب المرء لا يحبه إلالله، وأن يكره أن يعود في الكفر بعد إذ أنقذه الله منه كما يكره أن يقذف في النار"
     '' awon iroyin meta kan, enikeni ti o ba nbe lara re yoo ri adun igbagbo: ki o je pe Olohun ati Ojise Re ni o feran ju gbogbo nkan lo, ki o ma nife eniyan nitori Olohun nikan, ki o korira ki oun pada sinu ise aigbagbo leyin ti Olohun ti mu kuro nibe, gege bi o se korira ki oun wo ina '' (Al Bukari ati Muslim).
       Inife Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) je ki o di oranyan lati nife awon ti Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ba nife, gege bi awon molebi re ati awon omoleyin (sahaba) re (Olohun ki o yonu si won), bakan naa mima korira awon ti o ba korira, ati imu lore awon ti o ba mu lore, ati mimu lota awon ti o ba mu lota, toripe ki i nife tabi korira ayafi nitori Olohun.
13-    Imo pepe ati pipolongo esin re fun awon eniyan, ati mimu de etigbo awon ti won mo nipa re, bakan naa mimo se itaji sunnah re pelu ogbon ati wasi ti o dara, pelu mimo ko awon alaimokan tabi sise itaji fun eni ti o gbagbe, pelu sise iranlowo fun eni ti nba tele. Eleyi wa ni ibamu si oro Olohun ti ola Re ga ti o sope:
[ادْعُ إِلَى سَبِيلِ رَبِّكَ بِالْحِكْمَةِ وَالْمَوْعِظَةِ الْحَسَنَةِ وَجَادِلْهُمْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ]
     '' Pe ipe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ati wasi ti o dara, ba won jiyan pelu eyi ti o dara (ni oro), dajudaju Oluwa re ni o mo julo nipa eniti o sina kuro ni oju ona ti Re, atipe oun naa ni o mo julo nipa eni ti o mona '' Q16:125.
      Ati oro Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ti o sope:
" بلغوا عني ولو آية "
     '' e mu (oro mi) de etigbo awon eniyan, bio tile se ese oro kan '' (Al Bukhari).
15- Idabobo iwo re ati sunnah re pelu kiko gbogbo oun ti won ba so nipa re ti ko si ri be, pelu sisalaye eyi ti o je ododo fun eni ti ko mo, bakan naa ni didabobo sunnah re ati ipepe re pelu mimu awon iruju ti awon ota esin oniketa ba so po mo.
16- Didiro mo sunnah re, nitori oro re ti o so bayi pe:
" فعليكم بسنتي وسنة الخلفاء الراشدين المهديين, عضوا عليها بالنواجذ (الأضراس), وإياكم ومحدثات الأمور, فإن كل محدثة بدعة, وإن كل بدعة ضلالة " (مسند الإمام أحمد)
     '' sunnah mi ati awon arole eni imona olufini mona dowo yin, e fi eyin ogan yin di mu, e so ra fun asese muwa, dajudaju gbogbo asese muwa ni adada a le, dajudaju gbogbo adada a le ni ona anu '' (Ahmad).

Ni ipari:
 Lamartine akorin ewi omo ile faranse so nipa Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ninu oro re bayi pe: '' ko sele ri ninu itan omoniyan, yala ni rowo rose tabi tipatipa, iru ojuse ti o lagbara bayi, ojuse yi koja oye omoniyan, oun ni o mu opin ba awon ona anu ti o je gaga laarin omoniyan ati Adeda re, pelu re ni Olohun se ni asopo pelu omoniyan ti omoniyan naa si ni asopo pelu Olohun, oun ni o da sise afomo ati imona mimo Olohun ti o leto si ijosin pada laarin idarudapo awon orisa repete ti awon eniyan njosin fun ni igba naa. Ko sele ri rara ki enikan ninu eniyan doju ko ise ti o pe gbogbo eniyan nija pelu awon irinse to kere, toripe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) gbarale ara re nikan lati se aseyori lori ojuse nla yi, ko si eni ti o ran an lowo lori ojuse naa ju awon onka kekere ninu awon okunrin ti won ni igbagbo ninu re lo.
     Ni akotan, ko sele ri pe enikan ninu eniyan ni iru aseyori lailai ti ko legbe bayi ri ninu itan omoniyan. Toripe ko to ogorun odun meji leyin ti Islam ti bere ti o fi kari gbogbo erikusu ile larubawa pelu igbagbo ati nkan ija, leyin naa ni o ja ile Faris (Iran), Khorasan ati awon ile ti nbe laarin An naharain (Iraq) ati iwo oorun India pelu Suria ati Habash (Ethiopia), bakan naa gbogbo apa oke oya ile Afirika ati opolopo erikusu okun Mediterranean, ati ile Spain ati apakan ile France.
      Ti a ba woye si titobi afojusun yi, kikere awon irinse re , ati bi aseyori to seni lenmo, awon nkan meteta wonyi ntoka si ije akanda eniyan re, tani eni naa ti yoo se afiwe enikan ninu awon eekan eniyan ti o se deedee Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ninu itan? Gbogbo awon akoni wonyi ni won se agbekale yala nkan ogun tabi ofin atowoda tabi ijoba alagbara nikan soso, won ko fi lele ayafi aworan oun aye nikan, oun ni won ma nri ni opolopo igba ti o si jepe oun naa ni erongba won.
      Sugbon arakunrin yi (Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba)), ko gbe omo ogun, ilana, ofin esin, ijoba, awujo ati imuni leru nikan soso kale, bikosepe o tun ta awon eniyan ti o to egbegberun lona egberun ji ninu awon ti ngbe aye ti onka won ju ida kan ninu idameta agbaye lo ni asiko naa, koda o tun ta awon asiwaju, awon enimimo, awon esin, awon irori, awon adisokan ati awon emi naa ji, lori imona Al kurani, eyi ti ikookan ese oro re (ayat) wa di ofin mimulo, o gbe ijo kan ti o ni asepo ti o yanju pelu Olohun kale, ti awon eniyan lati orisirisi eya, awo atede ti nse asepo.
      O fi isesi kan pataki sile fun wa, eyi ti ko le pare lailai ninu esin Islam, oun naa ni ikorira mimu orogun (sise ebo) pelu Olohun, ati mimo josin fun Olohun Oba Okansoso ti oju ko le e ri. Bayi ni awon ti o ni igbagbo ninu Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se gba iroyin pelu diduro sinsin nibi titako awon olohun atowoda (gbogbo oun ti awon eniyan npe ni olohun leyin Olohun) ati ebo sise eyi ti o je iwa egbin si Olohun.       Gbigbagbo ida kan ninu idameta agbaye ninu esin re yi je ise iyanu re, tabi ki a so pe o je ise ti o ko lakaye lagara.
      Ironu nipa Olohun Oba Okansoso ti o pepe si laarin awon adapa iro ati itan aroso ti o ti gbile pelu amojuto awon alagbigba, oluwose ati awon ti ntoju awon orisa je ise iyanu kan fun ra re. O ni ikapani ni asiko ti o bere ipepe yi, ki won wo gbogbo ile ijosin awon orisa, ki won si danan si ida kan idameta gbogbo aye.    Dajudaju isemi aye re, ati ironu jinle re nipa aye, ati igbogun re ti ilana ebo ati ona anu ti o wa ni ilu re, ati aiberu re lori ibinu (suta) awon orisa, ati ini agbamora re lori inira fun odidi odun meedogun gbako ni ilu Makkah, ati nini suru re lori igbogun ti i awon eniyan re ati iyepere ti won fi kan an, de bi wipe won fe pa a, pelu gbogbo eleyi ko ye ko gbo lori ise ipepe re.
      Ati igbogun re ti awon iwa ibaje awoju ati awon isesi aimokan, ati igbagbo re ti o daju lori ini aseyori, ati pelepele re nigba inira, ati irera eni sile lasiko isegun, ati afojusun re eyi ti o duro deedee lori ironu kan ti ko ni asepo pelu wiwa ipo tabi iyi, ati irun re ni gbogbo igba, ati ima pe Olohun Oba re, ati iku re ati isegun re ti o lagbara leyin iku re, gbogbo eleyi nje ki o ye wa pe Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba) ki i se opuro ti o npe ara re ni oun ti ko je, atipe o je apere igbagbo ti o fese rinle ati amodaju ti ko ni iyemeji.
      Igbafa (ijura eni sile) re si fun un ni agbara lati fi esin re naa lele, o gbe adisokan re le ori ipinle meji: ije okansoso Olohun, atipe ki i se oun ti a le foju ri. Pelu eleyi lafi mo tani nje Olohun, elekeji, imo yi ni asopo mo oun ti o pamo (ti a ko ri). Amoye lo je, sorosoro, olusofin, akogun, olusegun, oluronu, ojise, oludasile esin ti o ba lakaye mu ati ijosin ti ko ni ere tabi orisa ninu, asiwaju lo je fun awon ogun ninu awon oba awon oba ori ile, bakan naa fun awon oba awon oba ti emi eyi ti ko ni ala, ni Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba) se. Ti a ba woye si gbogbo iroyin ti a fi ma nmo titobi eniyan, e je ki a bi ara wa leere, nje a wa ri enikan ti o ju Muhammad lo bi? ''
      Ire Ojise Olohun (ike ati ola Olohun ki o ma ba), mo nfi baba ati iya mi we fun o, wipe mo n jewo ara mi pe mi o pe iwo re bi o se to, mi o si pe eto re bi o se ye ninu iwe kekere yi. Gbogbo oun ti a ko yi ko ju itoka ati igekuru nipa ojise nla Muhammad (ike ati ola Olohun ki o ma ba), eni ti awon osebo ni aye atijo pare latara gbigbe dide re, ti gbogbo awon onifenu ati olojukokoro aye ati ifekufe igbesi aye eranko, ati awon ti won fe so omoniyan di eru won, ni gbogbo asiko naa yoo si ma teriba nitori re.
      Mo ngbero ni odo Olohun wipe ki iwe kekere yi je atunse fun awon oun ti won paro re mo eda alaponle yi, ki o si je isipaya fun alekun isewadi lati mo nipa eda pataki yi ti ntoni sona lo sibi gbogbo daadaa, ti o si nwani ni isora kuro nibi gbogbo aburu. Eni ti oro re ati ise re je ilana ati ofin ti a le ti ri iyonu Olohun Oba Onibukun Oba ti ola Re ga, ati lati wo Al jannah (ogba idera) Re, e je ki a pa ipase awon baba nla wa ti ko si lori imo ti, ki ipinle wa le wa lori imo, iwadi ati ironu ti o pe nibi gbogbo nkan ti a ba fe ma gbagbo tabi se ni ise.

 
www.islamland.com