SISE NINÁ AWỌN OBIRIN LEEWO NINU ISILAAMU

SISE NINÁ AWỌN OBIRIN LEEWO NINU ISILAAMU

SISE NINÁ AWỌN OBIRIN LEEWO NINU ISILAAMU
تحريم ضرب النساء في الإسلام بلغة اليوروبا

 

AHMOD AL’AMIR    ATI    TSAKURA FIFYAN
أحمد الأمير   و   تساكورا فيفيان

 

Itumo ni ede Yoruba
European Islamic Research Center (EIRC)
المركز الأوروبي للدراسات الإسلامية
& Ridwan Allah Murtadho
Atunto
Abd Ar-Razzaq Isa
 

www.islamland.com

 


بسم الله الرحمن الرحيم
Ni Orukọ Ọlọhun Ọba Àjọké́́́-aiye Ọba Asakẹ-ọrun
Ọrọ ìṣáájú

Gbogbo ope ti Olohun ni eni ti O ran Muhammad ni oniroodunnu olukilo, olupepe si oju-ona Olohun pelu iyonda re ati atupa imole, o si saponle awon saabe re o si fun won ni ola ti o tobi, ki ike ati ola Olohun ki o maa ba Anabi Muhammad ati awon araale re ati awon saabe re ike ati ola ti won yio ma tele arawon lopolopo.
Leyin na:
Paapa mo ko tira yi lati fi fesi si awon iruju awon ti esu tan je ti o si sowon nu ni isonu ti o tobi, paapa won ti fon ibere nipa lilu obirin ninu islam ka ni opolopo awon aaye ijoko, a si ri opolopo ninu awon ikanrin agbohun safefe ti nsalaye oro-esin lori alamori ti ko ni ogbon ati oye nipa re, opolopo awon oni keeta wa joko lori islam nibi alamori na nibi gbogbo ibujoko ti won nda adapa iro ati eri eke ninu awon oro ti ko ni afijo tabi ipile kankan, mo wa fe lati gbe e siwaju oluka alaponle ipó islam nibi nina iyawo ati ipo re si awon esin yoku ni iyapa ti o han. Islam ni esin kan soso ti o se nina awon obirin leewo yala nigba omode ni tabi agba. Eleyi ni alaye lekunrere lori oro yii, leyinna ki e wa se idajo lori alamori naa leyin kika ati iwoye si.

Onkowe.....
Ahmod Al’amir.
Pinpin awon ise nibamu si sheria Islam

Dajudaju gbogbo awon ise omo-enia yio je pinpin labe bogi islam pelu awon ipin ti nbo wonyi titi idajo awon ise sise larin ohun ti won se leto ati eyi ti won ko leto yio fi ihan:
1). Oranyan(Fardu): Ohun ni eyi ti o ga ju ninu awon ipele oranyan esin, ohun ni ohun ti Oba asofin nfe sise re ni fifi-rinle pelu eri dandangbon ti kosi iyemeji ati iruju nibe, gegebi ase irun-kiki, awe gbigba ati kike “Al-qur’an”, idajo re ni didunimo sise re ati mimu wa pelu sisan oluse re lesan ati jije olugbejusile ni’iya.
2). Eyi ti a fe(Mustahaabu): Ohun ni ohun ti Oba-asofin pase re ti kii se lojupanna dandangbon, ti won yio san oluse re lesan ti eni ba gbe jusile ko si ni gbese, lapejuwe; rirun pako ni o ku die ki agberun (As-solat) ro.
3). Eleyi ti o to(Mubaahu): Ohun ni gbogbo ohun ti ko si esan fun sise re ko si siya fun gbigbe sile re, gegebi rinrin, ati gigun nkan ati ohun ti o jo mejeeji ninu gbogbo ohun ti won yonda nibe ninu awon ise ti a ba saaba nibi isemi ojoojumo.
4). Eleyi ti won ko (Makroo'): Ohun ni gbogbo ohun ti Oba-asofin ko ti kii se lojupanna dandangbon, ti won yio san eni ba gbejusile lesan nibi titele ase, won ko si ni je oluse re ni’ya. Sugbon won fe jijinasi re ati ikuro nibi gbogbo ohun ti o ko sinu ati awon ohun ti nbe ni ikapa re, ati aigbodo ma yiju sibe won ko si ni sesan tabi fi iya je oluse re, sugbon o seese ki pipara re ati didunnimo o se okunfa kikoja awon aala Olohun ati bibo-sinu ohun ti Oba abiyi Oba to gbongbon se leewo ninu awon ise.
5). Eyi ti won se leewo(Haramu): Ohun ni gbogbo ohun ti Oba-asofin ko ni ojupanna dandangbon pelu eri amodaju ti ko si iruju nibe, ti oluse re yio gbese, ti won yio si san olugbesile re lesan niti titele ase, ni apejuwe; sise mimu-oti leewo.
Sisopinya larin Ohun eto ati eewo:
Dajudaju mimo ohun ti oto ati sise opinya re kuro nibi eewo ni opo Islam ati itoka si igbagbo, o si sopo mo awon ise inu-okan gegebi o ti so po mo awon ise afarase, atipe ipile nibi gbogbo nkan ni eto ati iyonda, ko si eewo ayafi ti otito-oro taara ba wa fun jije eewo re, amo siso nkan di eewo ati siso o di eto ninu iwo Olohun ti ola Re ga ju lowa, nitori jije adeda re olureni, oluso nkan-dirorun, onidekun, O le se ohun ti o ba wu leto fun eda re, O si le hana ohun ti o ba wu fun won, amo titobi re ike ni o je lati odo re fun awon erusin re ati ola, O gbe eto ati eewo kale fun awon idi kan ti o ba lakai mu ti o nseri sibi anfani omo-enia funra-won, lori iyen Olohun (Oba abiyi Oba to gbongbon) ko se nkankan leto ju ohun ti o dara lo, ko si se nkankan leewo ju ohun ti ko dara lo.
Yiyipada ise lati ibi idajo kan bo si ibi idajo miran:
1). Yiyipada ise ti o leto lati ipo fife bo si ipo sise-leewo bakanna ni idakeji:
Ise ti o leto seese ki o yipada lo si ipo eewo nigbati won ba ri awon okunfa ti yio so o di ohun ti yio yipada ni ijiro fun ki o maa je ise to dara ti okan ma nfe lo si ibi ise-egbin ti o je inira fun emi. Lojuponna alaye eleyi, idajo sharia nibi mimarin-kiri ni awon oju-popo je eyi ti o leto, sugbon o seese ki idajo sheria nibi rinrin-kiri yii yipada lati ipo ohun ti o to lo si ipo eewo nigbati adajo sheria fun ilu ba gbe ofin rinrin-kiri leewo kale leyin agogo mewa ni apakan awon oju-popo tabi ni ilu ni wiwoye-si ise aabo ti o seese ki o pepe si ibi iparun eda.
Bakanna ni ise eewo naa seese ki o yipada losi ipo eto nigbati won ba ri awon okunfa ti yio so o di oranyan fun gbigba-emi-la kuro nibi iparun, gegebi oti mimu, oti mimu je eewo labe sheria sugbon o seese ki o di ohun eto nigbati ti omo-enia ba sonu ni inu-papa to wa di pe o fe parun lati ara ogbe ti ko si ri nkankan niwaju re ju oti lo, nigbana yio mu odiwon ti yio fi gba emi ara re la kuro nibi iparun ko si gbodo mu koja re.
2). Yiyipada ise oranyan lati ipo oranyan bo ipo eewo, bakanna ni ojuponna keji:
Ise oranyan seese ki o parada si ipo eewo, o si seese ki ise eewo o parada si ipo oranyan, lori iru ona ti a gba salaye si waju, irun kiki lapejuwe oranyan ni sugbon o seese ki o di ise eewo nigbati omo-enia ba nkirun ninu ila re ni asiko ti ile-riri ti o le gan ba nsele loo ti eni ti nkirun si ni amodaju pe oun le ba lo ti ko ba tete sa jade kuro ninu ile na !! kikoja-ala ni ara enikan nibi gige ese re l’apejuwe ise eewo ni, amo ti onisegun ti nse iwosan ko ba rii ona-abayo lati la alare ju pe ki o ge ese re lo, ti ko ba se be yio se okunfa iparun fun, nigbana gige ese alare ti di oranyan fun onisegun ti nse itoju, ti ko ba se be, onisegun naa yio di elese, eni-ibi ti yio si ji’ya lori ai ge ese alare naa.
3). Yiyipada ise ti won ko sise re lati ipo kiko bo si ipo ohun ti won fe, ati yiyipada ise ti a fe bo si ipo eewo: Ise ti won ko oseese ki o yipada si ipo ohun ti won fe tabi tun bo si ipo oranyan ati dandan. Kiko iyawo sile lapejuwe je ise kan ti won korira ninu idajo sheria ti Olohun (Oba abiyi Oba to gbon-n-gbon) naa si ko o, amo ni apakan awon igba aiko iyawo sile le mu ni lo sibi awon eewo sheria ti enia ko ni le bo nibe ayafi ki o ko sile, gegebi ki o ma si itiju fun obirin (alaini-ijanu) ti (oko) si kagara lati se atunse re, ohun ti a le so nipa eleyi ni pe kiko re ni o lola ju, bee ni ise ti won ko naa le di ohun ti won fe.
O seese ki ise ti won fe yipada bo si ipo eewo, rirun pako (orin) lapejuwe je alamori kan ti won fe, o seese ki o di ohun ti won ko tabi di eewo nigbati ti eyin re le mo yo, ti o si mo pe ti o ba run pako eyin re yio yo, nibi isesi yi rirun pako yio maa lo pelu ofin sheria ninu islam eleyi ti o so pe (ma fi ara ni enia, ma si fi inira se esan inira).
Nisoki:
Nisoki ohun lori oun ti asalaye yi ni pe dajudaju islam kii se esin afoju ti ko riran ti ko mo odiwon ise awon enia ati awon ikapa won ninu isemi ati isemi ojoojumo, bi kii sepe oju-fifo ni ti otito-oro inu okan awon ota re ni o wa awon eni ti won nfe lati mo fon awon alamori ti o ruju ati awon oro-iro si inu islam ti won nfe lati pa ina esin Olohun (Oba ti ola Re ga ju), Olohun ko ni sai ma pe imole re, koda ki awon kefere ko jale.
Iwo aayo mi oluka o seese ki o ti ni ooye pe dajudaju islam kii se esin abosi bi kii se pe esin deede ni, deede si je ikan ninu awon oruko Olohun ti o rewa, sise leewo ati sise leto ninu islam won mo lori deede won ko mo lori oju-fifo, amo abosi pelu gbogbo iran re eewo ni labe sheria ninu islam.

Ibasepo iyawo labe itokasi Al-qur’an Alaponle ati Sunna tomọ kanga
Labe itokasi awon oro Al-qur’an alaponle a o ri pe dajudaju Olohun (Oba to gbon-n-gbon Oba ti ola Re ga ju) ti pase sise daada si iyawo ati sise aponle re, ati bibalo pelu daada, koda ki o ma si ife atokan wa nibe, Olohun ti ola Re ga ju so ninu tira-idajo re bai pe:
Itumo: (Ki e si maa ba won lo pelu daradara. Bi e ba korira won, o le je pe e ko ohun kan ti Olohun si ti se opolopo rere sinu re) Surotu An-nisai 19.
Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun o maa ba a – nso bai pe: “onigbagbo lokunrin ko gbodo maa korira onigbagbo lobirin, ti o ba korira iwa kan lara re yio yonu si iwa miran lara re.” Muslim.
Olohun (Oba abiyi Oba to gbon-n-gbon) nsalaye pe dajudaju o nbe fun obirin awon eto kan lori oko re, gegebi awon eto kan ti se wa fun oko re lori re, Olohun wa nso bai pe:
Itumo: (O wa fun awon obirin l’ori oko iru ohun ti o wa fun oko won l’ori won pelu daada) Surotu Al-baqaroh 228.
Asoole ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ni asiko ti ipakoda re sunmo ni nini akolekan pelu awon obirin ati sise aponle won ati aigbodo mo se abosi won ati dida awon eto nu. O so bai pe: “E maa se daada si awon obirin.” Muslim.
Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun o maa ba a – tun so bai leekan si pe: “Eni ti o pe ju ninu awon onigbagbo ododo ni igbagbo ni eni ti iwa re dara ju, eni esa inu yin ni eni ti o dara si awon obirin re.” Tirimisi ati Ibnu majah 1230.
Lati odo “Aisha” – ki Olohun o yonu si – so pe: Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai pe:”Eni ti o loore ju ninu yin ni eni ti o dara si awon araale re, emi si ni eni ti o dara ju si awon araale mi ninu nyin.” Ibnu hibban ati Tirimisi 3314.
O tun pase sise suru lori awon asise re ati nini agbamora lori awon adínkù re ati amojukuro fun awon ohun ti o ba bo fun. Bakanna ni nsalaye adamo obirin eleyi ti Olohun seda re le lori. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun o maa ba a – wa so bai pe: “Dajudaju won seda obirin lati ara egungun efonha to te kokoro, ko le na fun o tan yan-yan, ti o ba wa gba itelorun pelu re oo gbadun re pelu aina-tan re, ti o ba wa ngbiyanju lati naa gbooro oo kan, kikan re si ni kiko-sile re.” Muslim.
O tun so bai – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe: “E maa se daada si awon obirin, toripe dajudaju won seda won latara egungun efonha ti o te kokokro, dajudaju ohun ti o te ju ninu egungun efonha ni oke re, ti o ba fee na a, oo kan, ti o ba fi sile ko ni ye ni tite kokoro, e ya maa se daada si awon obirin.” Al’bukhori.

Nje ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ná ikankan ninu awon iyawo re ri bi ?
Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ni awokose awon musulumi, Olohun se titele oju-ona re ni dandan fun won, (Eni ti ola Re ga ju) wa so bai pe:
Itumo: (Dajudaju ikose rere mbe fun nyin lara ojise Olohun fun eni ti mberu Olohun ati ojo ikehin ti o si ranti Olohun ni opolopo igba) Surotu al’ahazab 21.
Oun ni apejuwe ti o ga ju ati iwa ti o dara ju Olohun gbe e dide pelu esin irorun, Olohun re ko ni eko, O si se kikoleko re ni eyi ti o dara ju, awon iwa alaponle ati awon adamo ti o dara ju lo pejo si ara re, Olohun ti ola re ga ju so bai pe:
Itumo: (Atipe dajudaju ire je eni ti o ni iwa ti o dara ju) Surotu Al-qolam 4.
O lo awon iwa re alaponle niti fifi sise se lori ile, o si se e ni eyi ti awon enia nri ti won tun fara kin i, pelu oro re – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe:”Won gbemi dide ki nle ba pe awon iwa alaponle.” Moliki ati Bukhori 45.
Iyawo re “Aisha” – ki Olohun o yonu si – na nso ohun ti o mo nipa re ni abala opolopo ibase ninu eyi ti awon saabe re mo nipa re pe: “Alqur’an ni iwa re.” Ahmod lo gba a wa (4811).
Tabi ni itumo pe: O ma ntele awon ase re, o ma njina si awon ohun ti o ko, ko si iwa eleyi kan ti Alqur’an se ni loju oyinyin sibe ayafi ki Annabi je eni ti o pe ju ninu awon enia nibi fifi se iwa hu, ko si iwa buburu kan ti Al-qur’an ko o ayafi ki Anabi je eni ti o le ju ninu awon enia nibi jijina si i.
Ko wa ninu itan re – ki ike ati ola Olohun o maa ba – pe ona obirin tabi omode kan ri !!!!
Dajudaju eniti ba ma ntele itan re ati ti ba ma nronu si awon oro re abiyi yio ri pelu ojise Olohun (ki ike ati ola Olohun o maa ba a) nko nina obirin osi hana re in ihana ti otobi, iyawo re A’isha – ki Olohun o yonu si – nso nipa re pe: “Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ko fi owo re naa nkankan tabi obirin kan tabi omo-odo kan ri, ayafi ki o sa ma gbiyanju si oju-ona Olohun, won ko fi suta kan ri ki o wa gbesan lara onisuta naa, ayafi ti won ba ko lu ohun ti Olohun se ni eewo, igbana ni yio wa gbesan fun Olohun (Oba abiyi Oba to gbon-n-gbon).” Muslim lo gba a wa.
Bakanna ti o fi mo awon ota re ti won ngbiyanju lati ba ipepe re je ati lati dina mo o, won ri nkankan lati se atako ohun ti aso yii rinle.
Ki a tun woye si ohun ti eni ti o sunmo julo so nipa re, ko si iyemeji nibi pe sise idunnimo yio ma salaye adamo eniti o ndunni mo ati iwa re, omo-odo re “Anas omo Malik” – ki Olohun o yonu si – eniti o se boyi sin fun ojise Olohun fun odun mewa, nso nipa re bai pe: “Mo se boyi sin ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – fun odun mewa, ko seesi so fun mi pe: sio re ri, ko si so si ohun ti mo se ri pe: Bawo loti se eleyi ? Tabi so o si ohun ti mo ba gbe ju sile pe: Kilode ti o fi fii sile ? Ojise Olohun je eni ti o dara ju niwa ninu awon enia.” Muslim ati Tirimisi.

Idajo niná iyawo ninu islam
Dajudaju ipile sheria islam ni awon tira Olohun ti ola Re ga ju ati ilana Anabi re " ki ike Olohun ati ola re o maa ba a ati awon araale re ati awon saabe re "alaponle eyi ti egbawa re dara. Lati inu mejeeji ni a o ti ma mu eri, ni abe imole mejeeji ni a o si ti ma salaye idajo nina awon obirin ninu islam. Nje ninu oranyan ni, tabi ohun ti a fe, tabi ohun ti o to, tabi ohun ti won ko, tabi ohun ti won se leewo ninu agboye hadisi eleyi ti “Iyasu omo Abd Allah” gba wa nibi ti o ti so pe: Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai pe: “E ko gbodo maa na awon eru Olohun lobirin, ni Umar ba wa si odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – o wa so pe: Awon obirin ti ngbonmu si awon oko won” ni o ba se idekun fun won lati ba won wi, ni opolopo awon obirin ba wa rokirika ile ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun ki o maa ba a – ti won npariwo awon oko won, ni ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o ma ba a – ba so bai pe: “opolopo awon obirin ti wa rokirika ara ile Muhammad ti won pariwo awon oko won, awon won yi kii se enia to dara ju ninu yin.” Abu Daud lo gba a wa ati Ibnu majah ati Ad-darimi, o dara lodo Albani.
Ni inu sise alaye hadisi abiyi ti o gba waju yi, awon ohun ti nbo yi yio ye wa yeke:
Dajudaju hadisi abiyi yii, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a –ko so ni aaye kan ati asiko kan ninu igba, bi kii se pe sso ni asiko meta ninu igba ti won yato si ara won:-
Asiko igba alakoko: O so nibe – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe: “E ko gbodo maa na awon eru Olohun lobirin.”
Lori eleyi, gbogbo eniti o ba gbo oro yii lodo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – yio mo amodaju pe dajudaju idajo nina obirin ninu islam ohun ti won se leewo ni nitori kiko o re lati odo Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – atipe eni ba nse be elese ni, yio gbese titapa si ase ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a -.
Asiko igba eleekeji: Wiwa Umar omo Khottob – ki Olohun o yonu si – ni asiko kan ti o yato si asiko ti Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – soro nibe pe: “E ko gbodo maa na awon eru Olohun lobirin.” lati pariwo awon obirin sita pe: Awon obirin ti ngbonmu si awon oko won. Ni itumo pe; awon obirin ti nsaya gbangba, ti won si ngbonmu, ti won si ndoju awon oko won bole, bayi ni ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ba se dekun nibi biba awon obirin wi, niti lilo irori re ti o gboye nibi ohun ti nsele lowolowo ati awon bukata isemi ti nsele ati ohun ti o je pe ibalopo took-taya ko le duro deede ayafi pelu re. A mo bawo ni ibawi yi yio ti ri ? eleyi ni ohun ti a o mugbo leyin asiko die nibi iwadi ti nbo.
Asiko igba eleeketa: Leyin iyonda ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – fun awon oko lati ba awon iyawo won wi awon ti won gbonmu ti won si saya gbangba si awon oko won, opolopo awon obirin wa lo si odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – ti won pariwo awon oko won lo si odo re, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – wa so pe: “opolopo awon obirin ti wa rokirika ara ile Muhammad ti won pariwo awon oko won, awon wonyi ki se enito dara ju ninu yii.”
Ni asiko igba ikehin yii idajo ikehin fun nina awon obirin ninu islam wa foju han pe; ohun ti a korira re ni tabi ohun ti a se leewo ni, nigbati oko ba koja aala Olohun nibe. Eleyi ohun ti a o pada salaye re leyin-o-reyin. Nje won gboye ninu oro hadisi naa pe dajudaju ojise nla Muhammad – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – seni loju kokoro lori nina awon obirin bi ? Tabi o se eyin lori eni ti n na iyawo re bi ? dajudaju oro re – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – eebu nbe nibe ati fifagile riri ore fun eniti ba n na iyawo re !!!
Paapa awon saabe – ki Olohun o yonu si won – ti ni agboye eyi ti o se deede oro ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – won mo amodaju pe eniti ba n na iyawo re ko le ri iyonu ati oju-rere ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a -, ko si siyemeji nibi pe ohun ti ko ba yo ojise Olohun ninu yio ko sinu ohun ti won kanpa mo kiko re leyi ti o seese ki o di ohun ti won se leewo.
Koda nigbati “Fatimo omo Qaysi” ko oko re sile, awon ti won fe lati fi saya ba soro leyin igbanan, lara won ni “Mu`awiya” ati “Abu Jahm” ati “Usamoh omo Zaid”, ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – wa so fun nigbana pe: “A mo Mu`awiya okunrin ti o tosi ni ko ni owo lowo, a mo Abu Jahm o ma n na obirin gan, sugbon Usamo omo Zaid..” Ni obirin naa ba so bai leni ti nfowo juwe pe: Usamo! Usamo.”Sohihu Muslim.

Nje o rorun ki niná obirin o yi pada lati ipo ohun ti won kọ bọ si ipo ohun ti won se leewo ?
Paapa a ti ri ipile ati idajo alakoko ninu islam nibamu si nina obirin pe ohun ti won se ni eewo ni leyinna ni o yi pada si ipo ohun ti o to fun awon okunfa ati awon ipepe kan ti a sadayanri, leyinna ni o yipada si ipo ohun ti won kanpa mo kiko re gan, sugbon igba wo ni nina obirin yio je eewo ? Nina obirin yio je eewo nigbati o ba je ikoja aala ti ko nidi. Gbogbo aworan ikoja aala ninu islam eewo nigbati o ba je pelu abosi ati ikoja aala. Olohun ti ola Re ga ju so ninu Tira Idajo Re ni Eni ti nwa wa ni’sora kuro nibi gbogbo iran abosi pe:
Itumo: (Enikeni ti o ba se abosi ninu yin A o fun u ni iya ti o tobi to wo) Surotu Al’furqon 19.
Ojise Olohun-Ki ike ati ola Olohun o maa ba a nso bai pe: “e paiya abosi ni sise, dajudaju abosi sise ninu awon okunkun ojo igbende ni.” Muslim.
Lati odo Anas – ki Olohun o yonu si – o so pe: Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai pe: “E beru epe eniti won bosi, koda ko je keferi ko ni si gaga kankan ti o le di (epe re) lona.” Ahmod, o dara l’odo Albani.
Islam ko fifi suta kan enia eyikeyi tori o je pelu gbogbo aworan ati eya re koda ki o je oro-siso, fun oro Oba ti ola Re ga ju pe:
Itumo: (Dajudaju awon eni ti won da adapa iro mo awon adelebo ti nwon ko ara won duro kuro nibi isekuse ti nwon je olugbagbo ododo, A ti sebi lewon laiye ati l’orun, atipe iya ti o tobi mbe fun won.) Surotu An-nuur:23.
Tabi ki suta o je pelu ohun ti won nri pelu nina ati ohun ti o jo o ninu aworan suta ayafi pelu eto, fun oro Olohun ti ola Re ga ju to so bai pe:
Itumo: (Atipe awon eni ti nni awon onigbagbo ododo l’okunrin ati awon onigbagbo ododo l’obirin lara laije nipa ohun ti nwon se, dajudaju nwon ru eru iro ati ese ti o han.) Surotul’Ahzab 58.
Tabi ki suta o je jije ohun-ini pelu ibaje, Olohun ti ola Re ga ju nso bai pe:
Itumo: (E ko gbodo je ohun-ini yin larin ara yin pelu eru) Surotu Al’baqaroh 188.
Gbogbo awon abara ni won ri bakanná nibi eleyi ako ni ati abo, omo kekere ni abi agbalagba, musulumi ni abi keferi. Lati ọdọ Abu huraira lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a – pe: “Musulumi ni eni ti awon enia la nibi ahon ati ọwo re, olugbagbo ododo ni eni ti awon enia fi okan tan a nibi eje won ati dúkìá won.” Sun anu An-naami, o dara lodo Albania.
Eni ti o ba so pe dajudaju isilaamu nse ní lojú oyìnyín lori kì koja aala tabi sisọta tabi nina obirin o ti parọ mọ ẹsin Ọlọhun ni irọ ti o tobi.

Ofin idajo sharia Islam nibi niná obirin:
Idajo isilaamu nmu alamọri niná obirin ati fifi suta kan lati ọdọ ọkọ re ni mimu ti o le ati aifi owọ dẹngbere mu u pelu biba oko wi lori kiko ja aala pelu iyawo re, o si nlo ibawi yii ni lilo imo nibamu si ofin sharia nibi ìṣesí gbigbe irufẹ awon alamori be lo si ile idajo, ni apeere:
1). Iwe’royin Riyadh fonka si ori adirẹsi re ti onina lori ero aiye lujara(Internet) ni ojo 12/12/2012 iro to nbo yi:
Ile-ejo to nri si eto omo-enia ni abe akoso “Qotif “ni ilu Saudi Arabia se idajo lori oko-iyawo kan ti o koja aala lori iyawo re pelu fifiya je, pe ki won o na ni ogbon bilala ni gbangba walia ki o le je arikogbon fun elomiran ninu awon olurekoja aala lori awon iyawo won. Bakanna lo tun se idajo pe ki o lo ko eko fun ojo mewa ni okan ninu awon ile eko akanse to nri si abala bi a ti ngbe pelu iyawo ati ìṣesí awon ebi, ki o si tun se idanwo alafowo se ti won yio ko mo iwe ejo naa.
Lori aworan kan-na nibi alamori yi dajudaju gbogbo awon ile-ejo ni gbogbo ilu isilaamu ni i ma nje oko ti ba nkoja aala lori iyawo re ni iya. Ninu eyi ti o sowan ju nipe apakan awon obirin ma nse ideruba, ti won ma nkilẹ, ti won ma ndete si awon oko won, ti won yio fa apá si ara won ni apá ti o mo niwon, leyin na won yio gbe e lo si ago awon olopa lati sise to pipe oko won lejo niti abosi, lati yepere oko re ti ko m’ọwọ-m’ẹsẹ.
Eri oro nibi alamori naa nipe dajudaju musulumi, onilakai, eni ti ntele awon eko isilaamu ko ni yonu si sisabosi obirin ati kikoja aala lori re, gegebi o ti je pe esin wa ko ko wa tabi pa wa lase pelu eleyi, bi kii se pe o se ni eewo fun wa ti o si se ninu ohun ti abosi ati eewo ko sinu, o si pa wa lase sisamojuro, ati ki ija tan ninu-eni, ati suuru, ati isedekun fun-ni, ati fifi daada ti aburu lo. Ni amodaju nipe isilaamu ko se nina obirin ni alamori kan ti o leto, bi kii se pe o se ni ayafi ni awon aaye kan ti isemi loko-laya ko le rorun nibe ayafi pelu re, o si fi awon majemu kan de e ti yio so lilo sibe di ohun ti o sowon gan lati mu erongba kan soso wa si imuse; ohun ni sise isọ lori ile ati iwa rere ni awujo lapaapo.

Awon idajo sheria nibi ìṣesí orikunkun iyawo
Ti olusọro kan ba so pe: se ko wa dara ju fun okunrin lati se isiti fun iyawo re olorikunkun ju nina re lo ni, a o so fun pe bee ni, atipe eleyi ni idajo Olohun, Ẹni ti o ṣọ ninu Tira onidajọ rẹ bai pe:
Itumo: (Ati awon ti e nberu sise orikunkun won, e ṣe kilokilo fun won, e ta kete si ibusun won, ki e si lu won; sugbon ti won ba teriba fun nyin, e ko gbodo wa ọna (ija) pelu won, dajudaju Olohun je Oba-giga Olutobi) Surotu An-nisai 34.
Ojise Re alaponle – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – so bai ni asiko Hajji idagbere pe: “E teti gbo o, ki e ya ma se daada si awon obirin, oluranlowo ni won je fun yin, e ko nikapa nkankan lodo won ju iyen lo, ayafi ti won ba hu iwa-ibaje ti o foju han, ti won ba se be, e deye si won lori ibusun, ki e si na won ni nina ti ko ni apa nnu, sugbon ti won ba teriba fun yin, e ko gbodo wa ona (ija) pelu won. Ẹ teti gbọ o, eni eto lori awon obirin yin, awon obirin yin na si ni eto lori yin.” At-tirimisi, o dara lodo Albani.
Bai ni a se ri bi Olohun se salaye nibi idajo re ti o loore ju pelu lori ìṣesí awon erusin re, ati bi ojise Re alaponle se salaye ona iwosan isoro iyawo olorikunkun, o wa se iwosan yii pelu awon ipele meta:
1). Ipele alakoko:
Ki oko iyawo gba ona wasi ati isiti gegebi ona lati ṣàtúnṣe iyawo olorikunkun, ki o to lo si ona ideyesi lori ibusun, títò yi je oranyan lodọ agbarijopo awon Alfa onimo-ẹsin, o wa di oranyan fun okunrin lati fa ọkan iyawo re mora pelu oro pelepele ati mima fun gbọ ninu awon irọ ti yio ma mu ọkan lẹ, yio si maa mu mọ bi o ti je pataki to lọdó re, atipe o je eni ti o nifẹ daada. ki o si maa lo gbogbo ìkápá re sibi isiti fun ati sise waasi fun leni ti ngbiyanju lati se atunse ìṣesí re, ni amodaju pe waasi ti oba wa lati inu ọkan gbigbẹ ati pẹlu awon ile koko ko le sa nfaani, bi kii se pe pelu pẹlẹpẹle nibi orọ-sisọ ati ibagbe pelu pelepele gegebi rira ẹbun fun iyawo titi yio fi maa gbo oro si oko re lenu pelu iyọnu ọkan ati emin ti o dara. Pẹlu iwa yiI, o di ọranyan lori iyawo ti o ni lakai ti o si je oniwa rere ki o gba waasi lati enu oro ọko re, ko gbajumo ohun ti nbe ni iwaju re, nibi gbigbajumo awon ọmo re. A mo ti obirin ba je alagidi oniwa buburu ti isiti ko ni se ni anfani ati waasi ati itosona, ti oko ba lo gbogbo ìkápá re lori eleyi tan yio wa bo si ipele eleekeji nibi títò-tẹle gegebi Olọhun (Oba abiyi Oba to gbob-n-gbon) ti pa wa l’asẹ, ohun ni didẹye-si lori ibusun.
2). Ipele eleekeji:
Ki oko o gba ona ideye-si lori ibusun; ohun ni ki o koyin si lori ibusun ki o ma ba sere ni ibasere ọko-iyawo fun ọjo meta gegebi aala ti o pọ ju, fun orọ ojise Olohun– ki ike ati ola Olohun o maa ba a-ti o so pe “Ko leto fun musulumi kan ki o deyẹ si omo-iya re kọja ojọ meta.” Muata, won fenu ko le lori.
Titi yio fi je ki o furamọ pe oun ko yonu si ìṣesí re. Ona abayo yi ni ibamu si anfani keji fun iyawo lati ye ara re wo larin asiko yii ti se ojo-meta – anfani lati ronu, toripe ti o ba deye-si ju igba yii lo, pelu eleyi yio fiya je, ti o ba wa ye ara re wo to si seri pada sibi sise daada, o di oranyan fun u (oko) lati fagile dideye si i, ki o si samojukuo fun u, ko si ha asise re danu fun u, ti o ba n ba bẹẹ lọ, to nsagidi, to nsegberaga, to ngapa ti ko wa ri anfani dideye-si re si i, yio bo si ipele elẹẹkẹta.
3). Ipele ẹlẹẹkẹta:
Ti okunrin ba gbiyanju lati ṣàtúnṣe iyawo re olorikunkun pelu isiti,waasi, oro to dara ati awon ebun, sugbon ti ko se e l’anfani, leyin na o tun gbiyanju ona ideye-si lori ibusun ati sise afihan aidunu-si re si ìṣesí re, sugbon eleyi na ko tun se e ni anfani, nigbana ni won se niyonda fun okunrin lati ba iyawo re wi pelu nina a ni nina ti ko ni apá nnu ti ko si ni oripa. Paapa agbarijopo awon Alufa ti fenu ko lori oranyan ìtòléra-won yii gegebi ona abayo si isoro iyawo olorikunkun, ohun ni waasi leyin na ideyesi lori ibusun leyin na ni niná. Paapa “Atoou” ti so pe: Mo bi “Ibnu Abbas” leere pe kini niná ti ko ni apá nnu ? O so pe: Pelu orin (pakó) ati ohun ti o jọ!!. “Alhasan Albasiri” wa so pe: itumo re ni niná ti ko ni oripa”.
Nitori t’Olohun iwo ọre mi pataki to nka iwe yii, iru ọgbe wo ni pako le fa (ohun ni igi tẹẹrẹ kan ti gungun re ati kiki re ko ju deede gege-ikọwe lọ) ? Njẹ o rọrun ki won pe niná pelu rẹ ni niná ti o lagbara ti o si le koko. ?
Ti o ba ri si pe ti oko ba ná iyawo re ni niná to mọ niwọn pelu orin ni nina to lagbara, wa tele mi bakanna lati woye si melo-melo ninu awon ere-oritage awon gẹẹṣi ti won ngbe jade ni “Holand” ati ibomiran ti o yato si i, ti nya aworan fun wa ọrọ imunubini larin okunrin kan ati omiran, tabi larin okunrin kan ati obirin kan, tabi larin oga ìlèṣe ati awon osise abe akoso re, larin ere yii, ikan yio gbe ika-ilabe re si ori-igbaya elomiran leni ti nwa nisora tabi titi yio fi f’ika ifabẹla re ti danu tabi pelu gege-ikowe ti nbe lowo re ti yio fi kan a nigbaya, ni opolopo ninu awon asiko, ẹni yi le gba elomiran leti. Nibi opolopo ninu awon ere-oritage won; iyawo nibi oro siso pelu oko re le di eni ti yio gba oko re l’eti ni gbigba leti ti o lagbara abi larin iforo toro larin awon mejeeji ki oko re gba leti leyinna yio si peyin da. Gbogbo eleyi ni awon geẹsi ko ka a si ohun ti oun ibaje larin oko-laya, bi kii se pe o jẹ igbarata ti o mu oko tabi iyawo gba ikeji re leti. Won a si tun maa kaa si pe dajudaju okọ yii tabi iyawo yii je enikan ti o ni ọlaju, ni amọndaju pe gbigbani leti ninu isilaamu je eewo, won kan ntako Islam ni, won si nparọ mọ ọ pe o n seni lojukokoro lori ilekoko.
Pelu pe dajudaju isilaamu ti yonda fun okunrin eleyi ti o ti lo ìkápá re ni ipele alakoko ati eleekeji ki o bo si ipele eleeketa, bee naa ni Islam ti fun obirin ni eto kan siwaju bibo si ipele yii tii se bibere fun kiko-silẹ ti a mọ si itusile (khuliu`)
Ni amodaju pe awon ipele won yii; isiti, leyin na ni ideyesi leyin nipari ni niná kii sii se ona-abayo fun awon isoro ojoojumo larin oko ati iyawo, bi kii se pe ona atunse si awon isoro nla larin awon mejeeji. Ni apejuwe ti oko ba ṣọ fun iyawo re pe: se ireṣi ati ẹja fun wa loni, ni iyawo ba gbagbe lo ba se iresi ati adiẹ, nje won yio lo idajo yii sibi eto re yii, pe ki o se isiti fun u tabi ki o dẹyesi tabi ki o ná a ?!!!.
Ni otito ko ribẹ, eleyi ni awon alamọri ibasaaba ti o sọranyan ki o lọ pelu alafia ti ko gbodo si eebu nibe, a mo ti iyawo ba je obirin oniwa buruku olorikunkun ti oko si ti bẹre si ni ri i pe o ti fe ma se asise ati iwa aida ati iwa ẹṣẹ ati igberaga ati motomoto !! nibi yii o, ohun ti a le sọ nipa obirin olorikunkun yi ni pe o ni bukata si ki won o se atunse re ati itosọna ati iwosan si isoro re gegebi alaisan eleyi ti o ni bukata si óógún. Wa fi ori ya aworan re pelu mi iwo oluka, enia mi tootọ; mimo bẹ obirin na lori agidi re ati igberaga re ati mimo bẹ re lori awon ìṣesí eleyi ti o je pe lati ara re o le ba ile re je ti o si le ti be fa kikọ-silẹ. Paapa oko ti lo pelu re fun asiko ti o pọ pelu ipele isiti ati itosọna ati ideyesi lori ibusun, sugbon ko ti ẹ daun si gbogbo eleyi, ewo ni o wa lọla ju ninu mejeeji bai; se kiko-sile ni tabi niná ti ko ni ọgbé nnu ?!! Ti niná ba jẹ oun ti oju re da, ti ikọsilẹ si je eyi ti oju re fọ, dajudaju eyi ti o da lọla ju eyi ti oju re fọ lọ.

Itumo ati ohun ti gbolohun niná nda le l’ori ninu Islam
Siwaju ki awon eleto ati ajijagbarata fun awon ẹto omo-enia lagbaye to da si lile koko mọ iyawo ati awon ọmo, paapa Islam ti gbawaju nibi eleyi pelu si se e leewọ, o si ka eniti ba n si ẹlẹṣẹ ti o lẹtọ si íyá aiye ati ọrun. Eleyi je ofin to pe ju ofin ti ifiya je ni ko koja ile aye nikan, lati bi ohun ti o ju ẹgbẹrun ọdun kan ati irinwo lọ (1400) ni ojiṣẹ nla Muhammadu – ki ikẹ ati ola Olohun o maa ba a – ti ṣọ pe: “Musulumi ni ẹni ti awon enia la nibi ahọn ati ọwo re, olugbagbo ododo ni eni ti awon enia fọkan tan lori ejẹ won ati dukia won.” Ahmod ati Tirimisi ati An-nasahi, o dara o si ni alafia lọdo Albani.
Paapa o tun ti so bai lẹẹkan si – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – pe: “Kii se olugba lododo ni eni ti ba ma nsepe, ti ba ma nsẹbi le enia, ti ba ma nhuwa ibajẹ, tabi ti mo nsọrọ ibajẹ lẹnu.” Bukhori lo gba a wa, ati Tirimisi, o lalafia lọdo Albani.
O tọ fun onibere ki o bere pe kilode ti Islam fi sọrọ lori fifagile ilekoko ti o si tun se niná obirin olorikunkun lẹtọ ni asiko kanna ?!
Fun ìdáhùn si ibere naa, o sọranyan ki akọkọ salaye iyatọ larin ohun ti niná nda le lori ninu isẹmi wa ojoojumọ laiye isin yi ati itumo rẹ ninu Sharia. Ninu isẹmi wa ti asiko yiI, nigbati ẹnikan ba gbo pe okunrin kan na iyawo rẹ, nigbana ni aworan buruku ati ibanujẹ yio wa si inu irori re si ọko iyawo alagidi alabosi yii, ni eyi ti o le fa ki o maa yẹpẹrẹ iyawo re pelu gbigbaloju gbanipa, ati aworan kan si iyawo naa ẹni ti won se abosi re, eni ti kikọja-ala selẹ le lori ti ara re kun fun awon apá, ọgbé, ati orisirisi arunki. Eleyi ni itumo nina ni irori ti aba saa ba. A mo ti nba ṣọ fun ọ pe mo lu agogo ẹnu ilẹkun, se oo gbọye nigba yẹn pe mo kọja aala lara ilẹkun pelu lilu ?!! Tabi ti nba so fun ọ pe ma fi apejuwe lelẹ fun ọ, nje oo gbọye pe ma kọja aala lara apejuwe pelu fifi lelẹ ?!! Ajepe nigbana gbolohun niná ma nyi pada yanyan nibamu si lilo ninu ede ati nibamu si erongba eni ti nsorọ ati ipo re ati iwa re. Gbogbo eleyi ni yio ya aworan itumọ gbolohun niná sinu laika wa. Nitori eleyi dajudaju agboye gbolohun niná ninu Islam yatọ gedengbe si agbọye re nibi lilo wa ojojumo. Agboye niná nnibamu si agboye wa ojojumo eewọ ni, ise ẹṣẹ totobi si ni ninu Islam. Lori eleyi kosi ọna fun pipade agbọye mejeeji lailai, ikookan ninu won ntako ekeji ni. Ti a ba fe se deede osoranyan ki a ṣọ pe ko si niná iyawo ninu Islam won ko si yọnda re, bi kii se pe Islam kọ yiyeperẹ re ati sisaburu si tabi fifi ahọn buruku ba ṣọrọ. A mọ agbọye gbolohun niná ninu Islam ntumọ si niná kan gẹgẹ bi egígé to mọ niwọn bi a ti se apejuwe (bi lilu ago) leyi ti won kan gbero lati jẹ ki iyawo o mọ pe alasise ni oun nibi ẹto okọ re, atipe ẹto nbẹ fun oko re lati se atunse re ati lati mu duro deede. Paapa Islam ti gbe awon ipele ka lẹ fun oko lati fi koju isoro iyawo olorikunkun, ohun ni awon ipele ti o gbawaju ipele niná, o wa se niná ni ipele ti o kẹhin fun awon eni ti awon ọna abayọ miran ko ba sanfani fun. Paapa Islam ti gbe orisirisi awon ọna iwasọra kalẹ fun okọ, eleyi ti o jẹ pe ti o ba re kọja re yio di elẹsẹ olurekọja aala Olọhun ti yio lẹtọ si iya aiye ati t’ọrun, awon ipele na niyi:
Awon onde fun kikọni-lẹkọ pẹlu niná:
1). Lilo osirisi ona nibi wiwa ojutu si iṣoro: Ohun ni ki o lo ìkápá ati igbiyanju re sibi ipele meji to gbawaju niná nibi sise waasi ati isiti ati itọsọna leyin na ni didẹyẹsi lori ibusun.
2). Ki niná o jẹ pelu orin (pako) tabi ohun ti o jọ ọ, tii se igi tẹẹrẹ ti ko le kọja deede gege-ikọwe ni gungun ati kiki.
3). Kiko gbigba loju tabi gba ni awon aaye eewu ninu ara re: Dajudaju Islam se niná oju leewọ koda ki o jẹ pe ẹni ti won nna jẹ okunrin tabi obirin, ti o tun fi mọ awon ẹranko, oju je aaye ọwọ ti kikọlu re si ma nko suta ba awon aaye imọnkan ninu ara, bi won ti se e leewo bakanna; kikọlu awon aaye ewu ninu ara, ti o si fi ọwo lile mu eleyi. Awon iyen ni aala Olohun ti eni ba rekọja re ti di ẹlẹsẹ.
4). Ki kiko-lẹkọ kogbo je loju awon enia nibi eyikeyi ìṣesí ninu awon ìṣesí. Ko lẹtọ fun okunrin lati maa ná iyawo re niwaju awon enia, awon omo re, nitoripe iyepẹre nbe ninu eleyi fun obirin lakọkọ leyin na yio tun se okunfa ríre bu fun awon omọ lẹẹkeji, rire wo ni oko yi fi nre awon omo re to je pe o nná iya won niseju won tabi ni eti igbọ won ?.
5). Ki niná na o ma je eyi ti oni ọgbẹ nnu, ti oripa re yio han lara iyawo naa gegẹbi ki o gba ẹjẹ lara re, tabi ki o sokunfa ki o da ọgbẹ ati arunki si lara. Oko ti o ba da ọgbe tabi arunki si iyawo re lara ẹlẹṣẹ ni. Iru oko bẹ je eranko ọdaran ti ko fẹ daada fun iyawo re ju pe o fe ma gbẹsan lara re lọ ati lati sokunfa didaarẹ si lara lasan. Nibamu si sharia Islam osoyan ko foju ba ile-ejo lati fiya jẹ ẹ labẹ ofin.

Niná awon obirin ninu awon ẹsin miran
Dajudaju alamori nipa niná iyawo kii se alamori asiko kan tabi aaye kan ti o so pọ mọ igba kan tabi awujo kan ni pato bi kii se pe o nbe ni gbogbo awujọ ati nigbogbo igba asiko laisi ayafi. Eni ti o ba wa fẹ lati mọ nipa ipó obirin ni awon awujọ ti o ti re kọja, o mbe ọpolọpo iwe ti o sọrọ nipa abala yi ati nipa ipó obirin ni awujọ awon Yahudi “Jew” ati awon Roomu ati awon Saina ati awon India ijọun...titi de ìparí. Lori eleyi, bawo ni ẹsín Yehudi ati Nasara ti se pẹlu niná obirin ati eleyi ti o jẹ alamọri ti won ti ba saaba ti o si tan ka gbogbo awujọ ti o ti pẹ ti o fi mọ asiko asiwaju Mesia gan. Nje asiwaju Mesia – ki ọla Olohun o maa ba a - ṣọrọ nipa niná obirin rara bi?!!! A bi se won ri ninu iwe mimọ awon Nasara yala majemu lailai tabi tuntun awon ọrọ ti nṣọ nipa sise niná obirin ni ohun eewọ tabi ohun ti won kọ ?!! Ni ibi sise iwadi yio fojuhan pe kosi nkan ti ntoka si eleyi.
Ti Nasara(Kiristeni) kan ba ná iyawo re njẹ yio gbẹṣẹ bi ti won yio si fesu kan gegebi ẹlẹsẹ ni abala ẹsin. Ki wa ni ijiya re ni ibamu si awon ọrọ iwe mimọ ? Laisi fanfa kosi ese fun, nitori ai ri ọrọ kankan ti ntọka si eleyi ninu iwe mimo, majẹmu lailai ni tabi majẹmu tuntun!!
Bakanna won ko ni fi ẹṣẹ re bi ni abala ofin, won ko si ni fiya jẹ ayafi ti oripa ikọja aala lori iyawo ba fi ojuhan gẹgẹbi ki didalapa, tabi oju-apá, tabi ki o fi nkan ya l’ara. A mọ ti amin kankan ko ba foju han lara obirin naa, bawo ni yio ti wa fi niná re rinlẹ!!! Pẹlu itumọ miran, niná ti ko ba ni apá ko si ijile le lori labala esin ati ofin lọdọ won!!!
Bakanna ki a tun woye si ẹsin Yehudi, ati Buudhiyah(Buddhism), njẹ awon ọrọ ti nse niná obirin leewo mbe nibe ?!!!
Ni nti kosi iyemeji nbe nipe ko si eyikeyi orọ esin kankan ninu eyikeyii ninu ẹsin ti o se niná awon iyawo leewọ ayafi ninu Islam nikan!! Ti o fi mọ piparada niná iyawo lati ipó eewo bọ si ipó kikọ, dajudaju Islam ni ẹsin kan ṣoṣo ti o ṣọrọ lori sise niná obirin ni ohun eewo!! A mọ awọn ẹsin ti o ku, won ko mẹnu ba idajọ yi ni sanpọnna boya pẹlu sise e leewọ ni o tabi sise e ni ohun ti won kọ.
Bi o tun se jẹ pe eyikeyii ninu awon esin o mẹnu ba awon ounde tabi awon aala ti nbe fun niná obirin ayafi Islam, nitumọ pe ti oko-iyawo kan ti o jẹ nasara ba padanu ìkápá lori ẹmi ara re ni asiko kan ti o fi wa ná iyawo re, ki ni awon ounde tabi awon aala ti oje dandan ti kogbodo re kọja re ? Njẹ ẹsin Nasara sọ nipa awon aala ti mbẹ fun okọ nibi niná iyawo re, gegẹbi pe ko gbọdo ná oju rẹ tabi ki ogba ogbe lowo re.. ? Ni nti kosi iyemeji nbe ni pe ko si.
Oluronu si ohun ti nsẹlẹ lojoojumọ eleyi ti a nsẹmi nibẹ yio ri pe awon onka kan oni osuwon fun niná iyawo lati odọ awọn ọkọ wọn ninu awon Nasara tabi Yehudi tabi awon miran yatọ si won yatọ si awọn musulumi. Iwọ naa funra-rẹ lọ wo iwe akọsilẹ awon olopa ati awon isẹle ni awon ile-ẹjọ Amẹrika ati yurobu, oo ri awon onka ti ko se ka fun ọpọlọpọ awon okọ-iyawo ti won mo nlo lile pelu ẹbi,iyawo ati awon omọ wọn!!!
Koda awujo igba aimọkan siwaju Islam, awon larubawa ma nná awon iyawo won ni bilala gẹgẹbi won ti se n na ẹru, ti o si jẹ alamọri kan ti won ti ba saaba ti kii se ẹṣẹ, ti ki si se eewọ ninu ofin kankan. Sugbon nigbati won gbe Anabi muhammadu – ki ikẹ ati ọla Ọlohun o maa ba a – dide, o fagile alamọri naa ni fifagile ti o lagbara gan, o wa sọ bai pe: “Ẹni kọọkan ninu yin yio ma ná iyawo rẹ niti nina eru, ti o si see se ki o tun sun mọ ni opin ọjọ rẹ yẹn.” Bukhari ati Muslim.
Ninu hadisi yii, Anabi – ki ike ati ola Olohun o maa ba a – yọ alebu okunrin ti nná iyawo re lọsan gan fun, lẹyinna ti otun wa wa lalẹ ni ẹni ti ngbero lati sun mọ ọ!!

Awọn oro nipa ipó obirin lati inu iwe mimọ majẹmu lailai ati majẹmu tun tun:
Ni opolopọ igba ni awon leyin kristi ma nso fun wa pe dajudaju asaaju Al’mosihu(Jeesu) – ki ola Olohun o maa ba a – ni oludaabo-bo akoọkọ fun awon ẹtọ obirin, atipe oun ni eni ti o fun u ni awon eto ti eyikeyi ẹsin miran ko fun u, atipe dajudaju iwe mimọ gbe si ipo to se deede, o si se agbega ipo re !!! sugbọn se orọ yii ri bi won ti nso ?!!!
Gbogbo enia lo mọ pe dajudaju iwe mimọ se leewọ fun obirin lati wọ inu pẹpẹ inu sọọsi, ohun ni eyiti won fi ma nya awon ẹni mimọ si mimọ tabi aaye itọju awon iwe mimọ, yala obirin na jẹ ọmode ni, tabi ọdọ, tabi ọmọge, tabi agbalagba ṣiṣi, alamọri na ko nise pelu ọjọ-ori bi kii se pe pẹlu ẹya obirin. Iwe mimọ ko si mu wa si iranti yala ninu majẹmu lailai tabi tuntun eyikeyi itọkasi fun sise wiwọle obirin si inu amure (pẹpẹ), bakanna si won ko se ni iyọnda fun obirin lati ri asiri agbara awon awon alufa ijo lailai. Obirin kii se ẹni ti won yọnda fun lati maa sọrọ ninu sọọsi, kii si se ẹni ti won yọnda fun lati maa kọse eyikeyi bi won se ndi agba alufa ijo, ohun ti won se leto fun u ko ju lati kọṣe Shamosa tin se ipo boi sin!!! Paapa iwe mimọ ti kaa fun wa; awon iran agba alufa ijo ti gbogbo won si je lati inu okunrin, yala awon baba agba alufa ijo gẹgẹbi Nuhu, Ayyub, Ibrahim, Isiaq ati Ya’qub, tabi awon agba alufa ijo Aaroni tabi awon agba alufa ojise ijo ati awon arole won ati awon agaba alufa ijo oba Saadiku, gbogbo re pata pẹpẹ awon okunrin ni, ti o ba jẹ pe o lẹtọ fun obirin lati kose eyikeyi ninu ipo awon asiri pẹpẹ won yi, ko ba jẹ asaaju lobinrin Mariyama ẹni ti ọkunrin ko fọwọ ba ri, ni ko ba jẹ ẹni akọkọ lati kọse awon ipo asiri pẹpẹ won yi, sugbọn ni ibamu si awon ẹkọ ẹsin Nasara obirin jẹ ẹni ti won kọ fun nibi eleyi !!!
E je ki a mu oro die wa ọrọ wa lati inu iwe mimọ ki a le ri ipó obirin ati aaye rẹ:
1) Wọn yio jẹ obirin n’ya pẹlu ẹsẹ ọkunrin:
Iwe Jeremaya (34: 23): “Bi wooli kan tabi alufaa kan tabi enikeni ninu awon enia wonyi ba wi pe oun nje isẹ Oluwa, n oo jẹ oluwa re ati ile re niya.”
2). Didana sun obirin oni ṣina (pansaga):
Iwe Lẹfitiku (9: 21) “Ti Omọ alufaa lobirin kan ba ko ere bara re pelu sise agbere, dajudaju oti ko baba re naa mere, sisun ni ki won dana sun ọmọ náa.”
3). Gige ọwọ obirin fun awon idi ti ko ba lakai mu:
Iwe Deuteronomy (11: 25): “Bi okunrin meji ba nja, ti iyawo ọkan ninu won ba sáré wa lati gbeja oko re ti won nlu, ni oba na owo re ni o ba fa nkan ọkunrin ẹni ti ń lu okọ re yii, gige ni ki o ge ọwo re, o ko gbodo saanu rẹ rara.”
4). Obirin ti won kọ silẹ ati opó ati onisina (agbere) bakanna niwon:
Iwe Lẹfitiku (9: 21): “Enikeni ti o ba jẹ alufaa agba....Obirin ti ko ba tii mọ okunrin ri ni o gbọdo fẹ ni iyawo. Ko gbodo fi opo se aya tabi obirin ti oko re ko sile, tabi obirin ti o ti mọ okunrin, tabi asewo; ko gbodo fe eyikeyii ninu won. Obirin ti ko tii mo kunrin ri ni ki o fe laarin awon enia re. Ki o ma baa so awon ọmọ re di elese laarin awon enia re; nitori pe emi ni Oluwa, to mo sọ ọ di mimọ.”
5). Titẹriba obirin ti won kọ silẹ fun ọkọ rẹ:
Iwe ti Bolisi kọ si awon ara efesu (22: 5): “Mo pe ẹyin obirin ki ẹ ya ma tẹriba fun awon ọko yin gegebi ti Oluwa, toripe okunrin ni olori obirin, gẹgebi Mesia bakanna ti jẹ olori ijo, o jẹ olugbala ara, sugbon bi ijọ ti ntẹriba fun Mesia, bẹẹ gẹlẹ ni ki awon obirin maa se fun awon ọkọ won nibi ohun gbogbo.”
6). Jijẹ dandan fun obirin lati dakẹ ninu sọọsi:
Iwe alakoko ti Bolisi ko si awon ara Korinti (34: 14): “Ki awon obirin yin ya mo panumọ ninu soosi, a ko gba won laye lati sọrọ, won ni lati wa ni ipo iteriba, gẹgẹbi ofin ti wi, bi nkankan ba wa ti won fe mọ, ki won bi awon ọkọ won ni ile. Itiju ni fun obirin lati sọrọ ninu soosi.”
7). Obirin ni okunfa iparun (anú):
Iwe alakoko ti Bolisi ko si Timoti (11: 2): “Obirin ni lati maa fi ifarabale kẹkọ pelu iteriba. N ko gba fun obirin lati jẹ olukọni tabi lati ni asẹ lori okunrin, ki obirin maa panumọ ni. Nitori Adamu ni akoko da, ti Efa si tele. Ki i se Adamu ni ogba itanje, obirin ni ogba itanjẹ ti o fi di ẹlẹsẹ. Sugbon a óo gba obirin la nipa ọmọ-bibi, bi awon obirin ba duro lai yẹsẹ ninu igbagbọ ati ife ati iwa mimọ pelu ikora-ẹni nijanu.”
8). Ijopomulero ọkunrin lori obirin:
Iwe alakoko ti Peteru kọ (1: 3): “Bakan náa ni ki ẹyin obirin máa bọwo fun awon oko nyin...Ewa yin ko gbodo je ti oun afi han bii irun-didi, ati nkan ọṣọ wura ti e ko sara ati asọ-igba. Sugbon ki ẹwa yin je ti ọkan ti ko han sode, ọkan irele ati iwa pẹlẹ. Eyi ni ẹwa ti ko le sa, eyi ti o se iyebiye loju Olohun. Bayi ni awon obirin mimo ti ri ni ati johun, bakanaa awon olugbara le olohun lobirin, won yio mo bọwọ fun oko won. Iru won ni Sara ti o gbọran si Abrahamu lẹnu ti o pe e ni “oluwa mi”.”
Iwe Jẹnẹsisi (16: 3): “Leyin naa Olohun wi fun obirin naa pe: “N óo fi kun inira re nigba ti o balóyún, ninu irora ni o óo maa bímọ. Sibẹsibe, lọdọ ọko re ni ifẹ re yoo maa fa si, oun ni yoo si maa se olori rẹ.”
9). Jiju obirin alagbere loko titi yio fi ku:
Iwe Dieteronomy (13: 22): “Bi enikan ba gbe omoge niyawo, sugbon ti o korira re leyin ti o ti ba a lopọ, ti o wa so pe o ti se isekuse, ti o si fi bee so o ni oruko buruku, ti o wa wi pe; Mo gbe obirin yii niyawo sugbon nigba ti mo sunmọ, nko ba a nile. Ki baba ati iya omobirin yii mu asọ ibale re jade, ki won si mu un tọ awon agbaagba ilu na lọ ni ẹnubode...Awon agbaagba ilu naa yoo mu okunrin yii, won yoo naa daradara, won yoo si gba ọgorun iwọn ṣekeli fadaka lọwo re fun baba omobirin na bii owo itanran,....Sugbon bi ẹsun ti won fi kan obirin naa ba je otito, pe won ko ba a nile, won yoo fa obirin na lọ si enu ona ile baba re, awon okunrin ilu yoo si sọ o ni okuta pa.”
Iwe Dieteronomy (22: 22): “Bi ọwo ba tẹ okunrin kan ni ibi ti o ti nba iyawo oniyawo lopọ, pipa ni ẹ gbodo pa awon mejeeji; ati okunrin ati obirin naa. Pelu eleyi ni won yio fi mu aburu kuro laarin yin.”
Iwe Dieteronomy (23: 22): “Ti okunrin kan ba ba odo-moge ti ko ti ri okunrin ri soro ife, ti okunrin naa wa ri ni arin-lu, ti o si ba a lopọ, ẹ mu awon mejeeji jade wa si enubode ilu, ki ẹ si sọ won ni okuta pa.”
10). Obirin wa ni ipo ti o kere si ti okunrin:
Iwe alakoko ti Bolisi ko si awon ara Korinti (3: 11): “Mo fe ki ẹ mọ pe Mesia ni ori fun olukuluku okunrin, okunrin ni ori fun obirin, Olohun wa ni ori Mesia. Okunrin ti o ba nsadura tabi ti o ba nwaasu ti o bo ori fi abuku kan ori re, sugbon obirin ti o ba nsadura tabi ti o ba nwaasu lai bo ori re fi abuku kan ori re, o dabi ki o kuku fa ori re, nitori bi obirin ko ba bo ori, ki o kuku ge irun re mọ le, sugbon ti o ba je itiju fun obirin lati ge irun re mọlẹ tabi lati fa ori re a je pe o ni lati bo ori re, ko leto fun okunrin lati bo ori re, nitori aworan ati ogo Olohun ni. Sugbon ogo okunrin ni obirin, nitori okunrin ko wa lati ara obirin; obirin ni o wa lati ara okunrin, atipe a ko da okunrin nitori obirin, obirin ni a da nitori okunrin. Nitori eyi, o ye ki obirin ni alasẹ ni ori re nitori awon angẹli.”
11). Awon ẹkọ Deskolia fun awon obirin:
Abawọle keji ninu Deskolia pelu akọle (o sọranyan fun awon obirin lati maa tẹri ba fun awon ọkọ won, ki won si maa dunnu si idajọ re) o nsọ bai pe: “Ki obirin ya maa tẹri ba fun ọko re toripe ori obirin ni ọko re,...Iwọ obirin yaa mọ paiya ọko re, ki o si maa tiju re, ki o si maa wa iyọnu re ni oun nikan soso lehin Olohun, gegebi a ti wi, se irọrun fun u nibi iranlọwọ re ki oko re naa le fa ọ mọra lọdọ re, ti o ba fe jẹ olugbagbọ ododo ati eniti Olohun yo yọnu si ma se maa ṣọṣọ lati baa mọ yọ awon okunrin àjojì ninu, ma se maa rankan lati wọ asọ ti awon enia yio fi ma nirankan si ọ tabi asọ fẹlẹfẹlẹ eleyi ti ko lẹto ju fun awon alagbere lọ ki awon eniti won ndẹdẹ iru awon olumura bai mọ ba moo tẹ le ọ. Ti o ba nbe ni eniti ki se iru awon iwa buruku iwa asise won yi, pelu ọṣọ re yi oun nikan ni ki o maa tẹba fun pelu oso re, toripe iwọ pelu eleyi; oo ma fitina awon eniti nwo e, ti won si ndede re, ki wa lo de ti ó o le para mọ ki o ma ba ko si inu asise yii, ki o si ma ba ko enikẹni si inu iyemeji tabi owú nitori ti ẹ, nigbati o ba se asise pelu mimọọmọ se ìṣesí yii iwọ naa ó pada subu, toripe iwo ni óo je okunfa fun kiko iparun ba ẹmi okunrin yi. Lẹyin na, nigbati o ba se asise lori enikan pelu ìṣesí yi ni ẹẹkan-soso, oun naa yio je okunfa nibi pe ki o sa sise lọdo ọpolopo enia, ti o si jẹ eni ti agbeele rẹ kere, gẹgẹbi iwe-mimọ ti nsọ pe: “Nigbati munafiki ba subu si inu awon aburu to pọ yio yẹpẹrẹ, yio si fa inira ati alebu fun un” gbogbo obirin kọọkan ti ba nse bai yo parun pelu asise yoo si maa dede e awọn ẹmi awon alaimọkan lai nidi. Ki o ya lọ mọ ohun ti iwe-mimọ sọ fun eni ti nda adapa irọ mọ awon eniti won nbe lori eleyi pelu ọrọ pe: “Won korira obirin bu ju iku lọ, eleyi ni eyi ti o jẹ panpẹ fun awon alaimọkan” Bakanna ni aaye mii o nsọ pe: “apejuwe bi ikan se ma njẹ igi, gẹgẹbe ni obirin bu se ma nko iparun ba ọkọ re” o tun nsọ bakanna pe: “O dara; ibugbe ti o ba nbẹ ni koro ni ori aja lọla ju gbigbe pọ pelu obirin odale lo”. Ẹ mọ fara we awon obirin eleyi, ẹyin obirin elesin mesia ti ẹ ba fe je onigbagbọ lododo, ni akolekan pẹlu ọko re ki o si maa wa iyọnu re ni oun nikan soso. Ti o ba nlọ loju ọna bo ori re pelu iborun re, nitori ti o ba ti bo ori re pelu aso itiju oni idabo-bo kuro nibi oju awon ẹni buruku, mọ se mo se ọṣọ si oju re ti Olohun da fun ọ, kosi nkan ti o le din ẹwa ibẹ ku, tori gbogbo ohun ti Olohun da ni o rewa gan, ko ni bukata si ọṣọ, nitori gbogbo ohun ti won ba ti le kun lori dídára yoo ma yi idẹkun Oba adeda pada ni, ti o ba nrin ki oju re o maa wo ilẹ, ki o si bo ara re ni gbogbo agbegbe, jina si ọre ayo ti ko lẹtọ pelu awon okunrin, ti í si ma nkopa ni opolopo igba nibi awon iwa pooki. Obirin onigbagbọ ododo kii mu awon okunrin ni aayo, ti o ba si bo oju re yio bo pelu iberu lati ma ba maa wo awon okunrin àjojì,...Eleyi ti o je oranyan fun ọ ti o ba je olugbagbọ ododo ni ki o maa sa fun gbogbo iran ohun ti ko ni anfani ninu, ati mima wo awon oju lọpolọpo...(Dajudaju ima gbe inu papa loore ju gbigbe pẹlu obirin alahọn gungun alaigbọran lọ).”

Niná obirin ni awon awujọ awon Nasara iwọ-ooru (Gẹẹsi)
Ọpolopo ninu awon ọta Islam ngbiyanju lati fọn awon iruju ka nipa Islam. Lara re ni alamori niná obirin, ti won nlo nibiyi amuga idan wọn ti won ba saaba, ti won yio mo mu ninu awon aaya Alqur’an alaponle ati lati inu awon Hadisi Ojisẹ - ki ike ati ola Olohun o maa ba a – oun ti yio ranwon lowo lori awon iruju won. Niná ninu Isilam, wọn yio so sanponna lai so pelu awon oun to ro po mo ni waju ati leyin ninu awon ọrọ lati le mo tan iruju-iro ka nipa Islam pelu ọgbọn-ẹwẹ buruku won ti ko wulo, to jina yanyan si otitọ ọrọ. Won ko ni akori oro ni pipe re, bi kii se pe won yio mu aworan die lara re ti yio mo wa sele pẹlu re agboye buruku lati se iranwọ fun won nibi awon adapa irọ won nipa Islam, ti won si npepe ape mora si odo ara won lori abalo daada pelu awon obirin ati awon iyawo won. Sugbon ni paapa won gboju kuro nibi awon otitọ ti nbọ yii:
Akọko: Dajudaju Islam ni ẹsin kan soso eleyi ti o tọka si ajọsepọ ifayabalẹ ati ifẹran laarin tọkọ-taya. Ohun na si ni ẹsin kan soso ti o kọ kikọja aala ati fifi suta kan- ni yala pẹlu ọro ni tabi pẹli ise, Olohun ti ola Re ga ju sọ bai pe:
Itumọ: (Atipe o mbẹ ninu awon ami re pe, O da awon aya fun nyin lati ara nyin ki ẹ le ba maa ri ifayabalẹ ati ifẹ lọdọ wọn.) Surotu Ar-ruum 21. Ni ti mimọ pe dajudaju ifayabalẹ ati ifẹran yii ko le e waye ayafi lati ara yigi ti o ni alaafia ti o si lẹtọ ti o ba ilana sharia mu.
Ẹẹkeji: Dajudaju Islam ni ẹsin kan soso eleyi ti o fagile niná obirin ati yiyẹpẹrẹ re ati mimaá fi oju abuku ati iyẹpẹrẹ wo ó lati ẹgbeje ọdun (1,400) ti o ti re kọ ja, ti o si ri eleyi gẹgẹbi abuku fun okunrin. Ti a ba se iwadi ninu iwe mimọ awon Nasara yala majẹmu lailai ni tabi majẹmu tuntun a ko nií ri itọkasi kan nibẹ ni eyi ti o sunmọ tabi eyi ti o jina nibi sise niná obirin leewọ.
Ẹẹkẹta: Dajudaju Islam se’ni loju kokoro lori ibalo ti o dara pẹlu obirin, gbogbo awon aaya Alqur’an ati awon hadisi abiyi ti oó nii se pẹlu ajọsepọ lọkọ-laya apakan won pelu apakan ń s’eni loju kokoro lori ibasepọ to rẹwa ati sise daada larin oko ati iyawo, apakan won si apakeji. Olohun ti ola Re ga ju lọ nsọ bai pe:
Itumọ: (O wa fun awon obirin lori ọkọ iru ohun ti o wa fun ọkọ lori won pelu daada) Surotu Al-baqarọh: 228.
Ẹẹkẹrin: Dajudaju Islam se awon ajọsepọ omo-enia paapa julo larin ọko ati iyawo ninu awon okunfa lati ri ẹsan daada ati laada lodo Olohun. Ojise Olohun- ki ikẹ ati ọla Olohun o maa ba á – nsọ bai pe: “Óo nií maa ná níná kan lati fi wa oju rere Olohun ayafi ki Olohun o san ọ lẹsan pelu rẹ, titi ti o fi mọ okele ti o nfi sẹnu obirin rẹ.” Won f’ẹnu ko le lori.
Ẹẹkarun: Dajudaju Islam se biba obirin wi lẹtọ gẹgẹbi ayafi ti kii se gegẹbi ipilẹ, ati labẹ awon majẹmu ti yio kọdi ọkọ nibi lilọ si ibi lulu gẹgẹbii ona-abayo, ayafi nigbati ko ba si ona abayo kankan mo fun lati ti aburu nu. Eleyi ni pe awon obirin ko si ni ori ìṣesí kan soso ni gbogbo asiko ati gbogbo awon awujọ ati awon idile. Ohun ti o seese ki o jẹ atunse fun awujọ kan, o le ma jẹ atunse fun awujọ miran, o tun seese ki o jẹ inira fun dipo ki o ṣàtúnṣe fun, ohun ti o ba je atunse fun bibalo pelu obirin kan le ma je atunse fun obirin miran ni awujo miran tabi ni asiko miran, gbogbo bi o ti wu ki o gbiyanju to lati fi ṣàtúnṣe re. Eleyi tun je lori kikenu Islam ati kikari re fun gbogbo ohun ti o seese ki o sẹlẹ.
Ẹẹkẹfa: Dajudaju alamori ija loko-laya inu ẹbi je oun ti fọnka gan ni ọpọlọpọ ilu. Melo melo okunrin kiristani iwọ-orun (gẹẹsi) ti o nfi suta kan iyawo re ni gbangba loju awon enia ni papa okọ ofurufu tabi ile ounjẹ tabi ni ile-ọti titi ti o fi mọ oju-ọna gbogbo enia loju awon ti won re kọja lọ. Eleyi kii se ohun ti o pamọ, koda o jẹ ohun ti won fi ntakurọsọ lori apakan awon irinsẹ ikede ti o jẹ alafihan tabi alafeti-gbọ. Bakanna melo melo obirin iwọ-orun (gẹẹsi) ni amẹrika ati kanada ati yirobu ati ọsirelia ti ngba agọ awon ọlọpa lọ lati fejo pe oko re sun lori pe onaa.

Titanka lulú ti o foju han ni awon awujọ iwọ-orun (gẹẹsi)
Lati salaye titanka ija loko-laya inu ebi ni iwọ-orun (gẹẹsi) eleyi ti npepe ọlaju ati idagba-soke ni nti boyii:
1). Titanka awon eto ati awon akojọ ti o jẹ ti ijọba ati eyi ti ki í se ti ijọba ni awon ilu Yurobu eleyi ti ndide si awon isoro fifi suta kan awon iyawo’le ati ilekoko inu ẹbi.
2). Awon ikede ti npara ni ori awon nkan igbohun safefe oni wiwo ati oni gbigbo, eleyi ti ngbe gbogbo ikoja aala awon ara adugbo lori iyawo alabagbe won ni kete isele naa.
3). Awon ibere won mo ndo ju re ko awon ara awujọ iwọ-orun (gẹẹsi) ni gbogbo-igba, ninu re ni:
* N jẹ o ti sẹlẹ si ọ ri pe ki o náa iyawo rẹ koda ki o jẹ ẹẹkan.?
* N jẹ o ri tabi gbọ ni ọjọ kan ti baba rẹ náa iya rẹ bi ?
* N jẹ o ti gbọ siwaju ri pe ọkan ninu awon ẹbi rẹ náa iyawo rẹ?
* Ń jẹ o ti gbọ siwaju ri pe ọkan ninu awon aladugbo rẹ náa iyawo rẹ ?
Ohun ti a gba lero nibi mimu awon ibere yii wa ko ju lati se afirinlẹ ifojuhan ifisuta kan awon iyawo-ile lati ọdo awon ọkọ won ti won jẹ elesin kristi ni gbogbo Yurobu ati Amẹrika ati Kanada ati Ọsirelia. Eleyi je ohun ti ofojuhan ti osi gbajugbaja ni awujo yii.
Nipari, yio han si gbogbo olooto enia, ọla Islam gbe fun obirin, atipe ohun ni ẹsin kansoso ti o gbọla fun un, ti o si gbe ipo re ga, ti o si se agbega fun un kuro lọdọ gbogbo ẹniti o ba fẹẹ ba apọnle rẹ jẹ, ti o si sọ ọmọluabi rẹ, ti o si se ikilọ ni ikilọ ti o lagbara lori sisabosi rẹ. Ojis Olohun- ki ikẹ ati ọla Olohun o maa ba a- ń sọ bai pe:”Mo ń se ikilọ fun nyin nibi ẹtọ awon ọlẹ meji; ọmọ-orukan ati obirin.” Ahmod ati An-nasai ati Ibnu majah ati ninu sohihi jamiu 2447.

 
 
www.islamland.com